Njẹ Ó Ha Bọgbọnmu lati Ní Igbagbọ ninu Ọlọrun Bi?
Ori 2
Njẹ Ó Ha Bọgbọnmu lati Ní Igbagbọ ninu Ọlọrun Bi?
Ọ̀KAN ninu awọn ibeere tí ó ṣe pataki julọ tí iwọ yoo nilati dojukọ ni pe, ‘Njẹ Ọlọrun ha wà bi?’ Ibi tí o bá pari ero rẹ sí lori eyi lè ní ipa lori oju-iwoye rẹ fun idile rẹ, iṣẹ, owó, ọna-iwahihu ati igbesi-aye funraarẹ̀ paapaa.
2 Bi a bá beere pe, ‘Njẹ Ọlọrun ha wà bi?’ ọpọlọpọ awọn eniyan ni yoo dahun nipa sisọ asọtunsọ ohun tí wọn ti kà tabi tí wọn ti gbọ lati ọ̀dọ̀ awọn ẹlomiran. Bi o ti wu ki o ri, iwọ tikaraarẹ yẹ ki o ronu lori ibeere naa. Ninu iwe rẹ̀ Man, God and Magic, Dr. Ivar Lissner ṣakiyesi pe iyatọ pataki kan laarin eniyan ati ẹranko ni pe eniyan kò ní itẹlọrun ninu kiki sísùn, jijẹun ati ki ô mú ara rẹ̀ gbona. Eniyan ní “agbara isunniṣiṣẹ ajogunba kan tí ó ṣajeji” tí a lé pe ní “ipo jíjẹ́ ti ẹmi.” Dr. Lissner fikun un pe ‘gbogbo eto ọ̀làjú iran-eniyan ni wọn ti ní gbongbo ninu ifẹ lati wá Ọlọrun.’ Nitori naa didojukọ ibeere naa niti gidi gan-an pe, ‘Njẹ Ọlọrun ha wà bi?’ jẹ ẹri kan pe iwọ kò tíì pa animọ pataki kan tì sapakan—ipo jíjẹ́ ti ẹmi rẹ.
3 Ọna wo ni o lè gbé e gbà lati pinnu yala ’ẹni tí ó dá agbaye tí ô si jẹ alaṣẹ rẹ̀ kan wà, Ẹni Giga Julọ kan,’ gẹgẹ bi iwe gbedegbẹyọ kan ti tumọ “Ọlọrun”? Ó dara, ọgbọn ironu fihan pe bi ’ẹni tí ô dá agbaye kan’ bá wà, awọn ami ibẹrẹ agbaye naa nilati wà, pẹlupẹlu ẹri iṣẹ-ọnà ati eto rẹ̀. Ninu iwadii tirẹ lori yala iru awọn
nkan bẹẹ wà, a kesi ọ lati ronu lori ohun tí awọn onìmọ-ijinlẹ nipa awọn ohun abẹ̀mí ti rí nipa iwalaaye ati ohun tí a ti kẹkọọ rẹ̀ nipa agbaye wa lati ọ̀dọ̀ awọn onimọ-ìijinlẹ nipa agbara iná manamana ati awọn onimọ nipa gbangba ojude ofuurufu tí wọn nlo awọn ẹrọ telescope ati awọn ohun miiran tí nṣe iwadii gbangba ojude ofuurufu.IWALAAYE RẸ—IṢẸ ÈÈṢÌ HA NI BI?
4 Eeṣe tí o kò fi bẹrẹ pẹlu ara rẹ? Nibo ni iwalaaye rẹ ti wá? Otitọ ni pe, a ta atare rẹ̀ si ọ lati ọ̀dọ̀ awọn obi rẹ. Ṣugbọn bawo ni iwalaaye ti ṣe bẹrẹ lori ilẹ-aye?
5 Ninu isapa kan lati mú iwalaaye jade wá ninu ile-iṣẹ ayẹwo awọn ohun ijinlẹ ati nipa bẹẹ ki a sì ṣalaye bi ô ti ṣe bẹrẹ, awọn onimọ nipa egboogi ti rán awọn iná tí nbùyẹ̀rìyẹ̀rì la aarin awọn afẹfẹ-atọwọda pataki kan kọja. Abajade kan ti jẹ ti awọn omiró amino (ìru awọn nkan keekeeke tí wọn jẹ ‘ògúlùtu ikọle’ fun ohun abẹ̀mí). Sibẹ, awọn omiró amino wọnni, kii ṣe ohun abẹ̀mí. Siwaju sii, wọn kii ṣe abajade èèṣì kan lasan; a mú wọn jade lati ọ̀dọ̀ awọn onimọ-ijinlẹ tí a ti kọ lẹkọọ labẹ awọn ipo tí a fi sabẹ iṣakoso ninu awọn ile-iṣẹ ayẹwo awọn ohun ijinlẹ ti ode-oni.
6 Iye tí ô ju 200 awọn omiró amino tí wọn jẹ ti adanida lô wà, sibẹ kiki awọn akanṣe 20 nikan ni wọn wà ninu awọn eroja ara tí nmunidagba (protein) tí ó wà ninu awọn ohun abẹ̀mí. Ani bi awọn omiró amino kan bá tilẹ lè jade wá lati inu manamana, tani ẹni tí é yan kiki awọn 20 tí a fẹ́ gan-an tí a rí ninu awọn ohun abẹ̀mí? Ati pe bawo ni a ṣe ṣamọna wọn ní ètò ìtòlọwọ̀ọ̀wọ tí ô tọna tí ô di dandan fun awọn eroja ara? Olùtúpalẹ̀ iṣẹ-iwadii Dr. J. F. Coppedge ṣiro rẹ̀ pe ‘ṣiṣeeṣe tí ó ṣeeṣe pe ki ifọsiwẹwẹ kiki eroja ara Kanṣoṣo pere wá lati inu eto lọna èèṣì niti omiró amino jẹ 1 ninu 10.’ (Eyiini ni numba kan tí ó ní 287 òdo lẹhin rẹ̀.) Ní afikun, ó tún tọkasii pe, kii ṣe òkan, ṣugbọn ‘iye tí ô kere julọ 239 ifọsiwẹwẹ awọn eroja ara naa
(protein) ni a beere fun fun iru iwalaaye ti elero-ori tí ó kere julọ.’ Njẹ iwọ ha rò pe iru ẹri bẹẹ tọkasi iwalaaye gẹgẹ bi abajade lati inu èéṣì afọju, tabi ó ha wá lati inu iṣẹ-ọnà kan tí ô jẹ ti ọgbọn?7 Tún ṣakiyesi iru ifidanrawo miiran kan tí a ṣe ninu ile-iṣẹ ayẹwo awọn ohun ijinlẹ tí a si polongo rẹ̀ ninu awọn iwe-irohin gẹgẹ bi “mímú iwalaaye jade.” Pẹlu ohun-elo tí ó diju pupọ awọn: onimọ-ijinlẹ ti mú ki kokoro tí ô kere pupọ julọ (virus) kan tí a mujade lati inu ohun abẹ̀mí kan tí wọn sì ya awọn ẹya-ara rẹ̀ sọtọọtọ. Lẹhin naa wọn tún ti mú, awọn ẹya wọnyi tí wọn si tún wọn so papọ pada lati di kokoro tí ó kere julọ kan. Bi o ti wu ki o ri, onimọ-ijinlẹ nipa ohun abẹ̀mí René Dubos ṣalaye ninu Encyclopaedia Britannica pe ô jẹ aṣiṣe gidi gan-an lati pe iru aṣeyọri bẹẹ ní “mímú iwalaaye jade.” Kò si òkan yala ninu awọn onimọ-ijinlẹ wọnyi tabi awọn ẹlomiran tí ó tíì ṣeeṣe fun lati mú ẹmi titun jade lati inu ohun alailẹmi. Kaka tí ìbá fi mú àbá naa jade pe iwalaaye wá lati inu èèṣì, aṣeyẹwo yii fihan pe “gbogbo awọn ohun-eelo abẹ̀mí” tí a nilo ki iwalaaye tó lè ṣẹlẹ “ni a nilati pese lati ọ̀dọ̀ ohun abẹ̀mí kan tí ó ti walaaye tẹlẹ.”
8 Ani ki a tilẹ sọ pe awọn onimọ-ijinlẹ tilẹ mú eroja tí nmu nkan dagba tí ô ní ẹmi wá lati inu ohun alailẹmi, yoo kàn wulẹ fì òntẹ̀lùú pe ohun abẹ̀mí kan tí ó jẹ oloye tí ô ti walaaye tẹlẹri ni a nbeere fun gẹgẹ bi agbara tí ndari nkan. Ó hàn gbangba pe, kii ṣe pe awọn eniyan dé sihin lati mú ki iwalaaye ṣẹṣẹ bẹrẹ lori ilẹ-aye. Sibẹ a ṣẹda iwalaaye, eyi tí ô ní ninu iwalaaye ti ẹda-eniyan. Tani ẹni tí ó wà nidii nkan yii? Awọn akọwe Bibeli ti igba laelae pari ero wọn sibikan tí ó yẹ fun ironu gidigidi. Ọ̀kan sọ pe: “Èémí ti Olodumare ni ô fun mi ní iwalaaye.” Omiran tún fikun un pe: “[Ọlọrun] tikaraarẹ̀ ni olufunni ní ìyè ní gbogbo agbaye.” *
9 Wiwo ara rẹ fínnífínní sii yoo ràn ọ lọwọ lati ronu siwaju sii lori eyi.
AWỌN CELL TIRẸ—ỌPỌLỌ RẸ—IWỌ
10 Iwalaaye nlukiki ninu ara rẹ, tí ó kún fun 100,000,000,000,000 awọn cell (ẹya-ara tintintin) tí ô kere pupọ. Awọn cell jẹ apakan tí ó jẹ ipilẹ ninu gbogbo ohun abẹ̀mí tí ô wà lori ilẹ-aye. Bi a bá ṣe fi pẹlu ifarabalẹ kẹkọọ rẹ̀ tô, bẹẹ ni yoo tubọ díjú sii tô bi a ṣe nrí i.
11 Ọkọọkan ninu awọn cell ti ara rẹ ni a lè fiwera pẹlu ilu olodi kan tí ô kere ju ohun tí a lè fi oju rí lọ. Cell ní ninu awọn apá tí wọn dabi orisun agbara lati mú okun-inu jade. Ile-iṣẹ ẹrọ ninu cell nṣe awọn eroja ara bii protein ati bakan naa hor-mone (omi ara tí nṣàn sinu ẹjẹ) fun ipinkiri si awọn ẹya-ara gbogbo. Ipa-ọna didijupọ tí nmú awọn eroja wọ inu ati jade kuro ninu cell tún wà nibẹ. “Awọn oníbodè” nṣọ́nà lati ṣakoso ohun tí ó bá mú wọle wá ati lati gbogunti awọn agboguntini. Kọkọrọ tí ó wà fun gbogbo eyi ni nucleus, “gbọngan ilu” ti cell. Ó ndari gbogbo awọn igbokegbodo cell tí ó ní awọn ilana eto iwa abinibi tí a ti ṣe silẹ ninu. Awọn kan lara ẹya-ara cell kere tobẹẹ géẹ tí a kò fi lè rí awọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wọn daradara pẹlu ẹrọ amú-nkan-tobi onina manamana alagbara 200,000. (Eèrà kan tí a bá mú tobi dé àyé yẹn, ní itumọ kan naa, yoo gùn kọja idaji ibusọ kan tabi 0.8 km.) Kinni ohun tí ó lè ṣalaye iru eto ati ìdíjúlù tí ó yanilẹnu tí ó wà ninu ọkọọkan awọn 100,000,000,000,000 cell ara rẹ?
12 Nigba kan iwọ jẹ ẹyọ cell bín-ín-tín kan tí a sọ di ọlẹ̀ ninu ile-ọlẹ̀ iya rẹ. Cell naa pín sí meji, lẹhin naa si mẹrin, ati bẹẹbẹẹ lọ. Nigba tí ó yá, awọn kan lara awọn cell wọnni di iṣan inu ẹran-ara. Awọn miiran di awọn oju rẹ, awọn egungun rẹ ati ọkàn-àyà rẹ. Bawo ni é ti ṣe jẹ pe awọn cell naa mú ọkọọkan ẹya-ara rẹ jade lakoko tí ô baamu gẹ́ẹ́ ati ní àyé tí ô ṣe gẹ́ẹ́? Eeṣe, fun apẹẹrẹ, tí awọn cell dagba di awọn eti nibi tí ó jẹ tiwọn, tí kii sii ṣe lori eékún tabi apá rẹ?
13 Ani ki o tubọ tilẹ wò ó fínnífínní sii. Ninu ọkọọkan cell o ní ẹgbẹẹgbẹrun lọna mẹwa-mẹwa awọn eroja tí nṣakoso tita atare iwa abinibi (awọn gene) ati DNA (okùn ẹmi), tí nsọ fun cell naa bi yoo ti maa ṣiṣẹ ati bi yoo ti maa mú iru-ọmọ jade. A ti sọ pe DNA tí ó wà ninu ọkọọkan cell ní isọfunni tí ó pọ̀ tó lati kún inu iwe encylopedia kan tí ó ní 1,000 idipọ iwe ninu. Oun ni ó npinnu àwò irun rẹ, bi yoo ti yá ọ tó lati dagba, bi ẹnu rẹ yoo ti fẹ̀ tó nigba tí o bá bú sérìn-ín músé ati ailonka awọn kúlẹ̀kúlẹ̀ isọfunni miiran nipa rẹ. Gbogbo eyiini ni a ’ti kọsilẹ’ ninu cell DNA kan ninu ile-ọlẹ̀ iya rẹ.
14 Ani gẹgẹ bi abajade isọfunni titun lori iwọnba awọn koko wọnyi nipa cell paapaa, ibeere wa ni pe: Niwọn bi kò ti jẹ pe awọn obi mọ-ọn-mò pese ilana agbayanu ti iwa abinibi tí a ṣe silẹ naa tabi cell, tani ẹni
tí ó ṣe e? Njẹ a ha lè fi ọgbọn ironu sọ bi ó ti ṣe wáyé laisi Oniṣẹ-ọnà oloye kan bi?15 Ninu gbogbo awọn ẹya-ara rẹ, boya eyi tí ó jẹ àràmàndà julọ ni eyi tí iwọ kò ní fi oju rẹ rí lae—ọpọlọ rẹ. Nkan bii 10,000,000,000 awọn cell ni wọn parapọ di ọpọlọ, tí ó pọ̀ ní ilọpo meji ju gbogbo iye awọn eniyan tí wọn wà lori ilẹ-aye lọ, Ọkọọkan ninu awọn cell wọnyi, ní ṣisẹ-ntẹle, tún lè ní ẹgbẹẹgbẹrun awọn isopọ pẹlu awọn cell miiran ti iṣan ọpọlọ. Aropọ iye awọn isopọ rẹ̀ kọja ohun ti a tilẹ lè ronuwoye!
16 Iwọ ti tọju araadọta lọna ọgọrọọrun awọn otitọ-iṣẹlẹ ati aworan sinu ọpọlọ rẹ, ṣugbọn kii wulẹ iṣe kiki ile tí a nto awọn nkan jọ sí. Pẹlu rẹ̀ o lè kọ́ bi a ti nta okùn ní kôkô, lati sọ ede ajeji kan, lati ṣe bread tabi lati súfèé. Iwọ lẹ̀ ronuwoye—bi akoko isinmi lẹnu iṣẹ rẹ yoo ti ṣe rí tabi bi eso kan tí ô ní omi ninu daradara yoo ti ṣe rí lẹnu. O lẹ̀ ṣe ìtúpalẹ̀ nkan ki o sì ṣẹda wọn. O lẹ̀ ṣe iwewee awọn nkan, ki o mmọriri nkan, nifẹẹ ki o si mú ki awọn ironu rẹ sopọ pẹlu ohun tí ô ti kọja sẹhin, tí ó jẹ isinsinyi ati ti ọjọ-iwaju. Ẹni naa tí ô ṣẹda ọpọlọ dajudaju ní ọgbọn tí ô ga pupọpupọ rekọja ti ẹda-eniyan eyikeyi, nitori pe awọn onimọ-ijinlẹ jẹwọ pe:
“Bi ẹrọ tí a ṣe lọna tí o galọla, tí ó wà letoleto tí ó si díjúpọ̀ lọna agbayanu yii ṣe nṣe awọn iṣẹ wọnyi jẹ ohun tí ó rúnilójú, awọn ẹda-eniyan lè má lé yanju awọn ọkọọkan oriṣiriṣi awọn ìrújú tí ọpọlọ nmú wá lae.”—Scientìfic American.
17 Ní rironu lori yala Ẹlẹdaa kan wà tí ô jẹ Ẹni Giga Julọ, maṣe gbojufo apá tí ô kù ninu ara rẹ dá. Awọn oju-iriran rẹ—tí wọn ṣedeedee, tí wọn si lagbara lati bá ipo titun mu ju ti ẹrọ ayaworan eyikeyi lọ. Awọn eti rẹ—tí wọn lagbara lati mọ oriṣiriṣi awọn ìrú, wọn sì lè fun ọ ní ọgbọn imọlara idari-itọsọna ati iwọn-deedee. Ọkàn-àyà rẹ—irinṣẹ tí ntú nkan jade tí ó jẹ ti agbayanu tí ô si ní awọn agbara tí awọn oniṣẹ-ẹrọ tí wọn dara julọ kò tíì lè ṣe eyi tí ô dabi rẹ̀. Ahọ́n rẹ, eto bi ounjẹ ti Pg18 ṣe ndà ninu rẹ ati awọn ọwọ rẹ, ki a kàn mẹnukan iwọnba diẹ pere sii. Oniṣẹ-ẹrọ kan tí a háyà lati ṣeto, ki ô si mú ẹrọ nla oniṣiro kan jade ronu pe:
“Bi computer kan bá jẹ eyi tí ó beere fun oniṣẹ-ọnà kan, melomelo ni yoo ti jẹ bẹẹ niti ẹrọ didiju ti ara-oun-eroja-abẹ̀mí eyi tii ṣe ẹran-ara ẹda-eniyan mi—eyiiyi si jẹ apá tí ô kere pupọpupọ julọ lara eto-iṣiṣẹ ìsálú-ọrun oniṣọkan tí ô wà letoleto?”
“ẸNI AKỌKỌ” LAGBAYE
18 Ní nkan bii 3,000 ọdun sẹhin ọkunrin kan ní Aarin Ila-oorun Ayé tí orukọ rẹ̀ njẹ Elihu sọ pe: Wo oju-ọrun ki o sì ronu.” *
19 Njẹ o ha ti ṣe bẹẹ ní alẹ ọjọ kan bi? Gbogbo eniyan nilati ṣe bẹẹ. Kiki 5,000 awọn irawọ pere ni a lè fi oju-iriran wa rí lailo ẹrọ kankan. Ìṣùpò irawọ ti Milky Way tiwa, bi o ti wu ki o ri, ní iye awọn irawọ tí ó ju 100,000,000,000 lọ. Melo si ni awọn iṣupọ irawọ bẹẹ tí ó wà? Awọn onimọ ẹkọ nipa ojude ofuurufu sọ pe ẹgbẹẹgbẹrun araadọta ọkẹ—kii ṣe awọn irawọ, ṣugbọn ti awọn iṣupọ irawọ ni wọn wà, tí ọkọọkan si ní awọn ọpọ billion awọn irawọ tirẹ̀! Ẹ wo bi awọn eniyan ti kere pupọ tó ní ifiwera pẹlu gbogbo eyi! Nibo ni gbogbo rẹ̀ ti wá?
20 Awọn onimọ-ijinlẹ ti ṣawari pe niṣe ni ó dabi pe awọn iṣupọ irawọ wọnni nfò lọ kuro lati ibi ìgbáríjọ kan. Ero-ori pupọ ninu awọn onimọ ẹkọ nipa ojude ofuurufu ni pe ní ẹgbẹẹgbẹrun araadọta ọkẹ awọn ọdun sẹhin, ìbúgbàù tí ó lékenkà, “ìbúgbàù alariwo nla” kan, mú ki agbara ati ohun kan bẹrẹsi tankalẹ lati di agbaye gẹgẹ bi a ti ṣe mọ̀ ọ́n. Idabaa ero-ori wọn yii kò ṣalaye ohun tí ô mú ki eyiini ṣẹlẹ. Ṣugbọn ó ní itumọ tí ó gba afiyesi kan ninu, eyiini ni, pe ibi ibẹrẹ kan wà, akoko kan nigba tí a bí agbaye.
“Lonii ẹnikan lè ní imọlara ayé imọ-ijinlẹ tí ngbọ̀n jìnnìjìnnì nititori awọn ẹri-ami ṣíṣẹ́jọ pelemọ fun ìbúgbàù alariwo nla kan gẹgẹ bi ibẹrẹ agbaye. Eyi gbé ibeere dide nipa ohun tí ó ti wà ṣaaju, ati pe igbagbọ awọn onimọ ijinlẹ tí ô fidimulẹ julọ ni a mìtìtì nipa mímú un wá si ifojukoju pẹlu àbàtì wọn lati dahun awọn ibeere tí wọn rekọja imọ ẹda-eniyan.—The Wall Street Journal.
21 Bẹẹni, fun awọn eniyan tí wọn kò ní igbagbọ ninu Ọlọrun, awọn ibeere tí nrúnilójú kan wà: Kinni tabi tani ẹni tí ó fi nkan tí ô wà naa sinu agbaye? A ha ṣẹda agbaye wa lati inu òfo ni bi? Niwọn bi a ti gbà pe ohun tí ó wà jẹ iru agbara kan, kinni orisun agbara naa?
22 Dr. Robert Jastrow, oludari Goddard Institute for Space Studies ti NASA, ṣakiyesi bayii pe: “Loju iru
ẹri-ami bayii, ero naa pe Ọlọrun kan wà tí ô ṣẹda agbaye jẹ eyi tí ô bọgbọnmu lọna ọgbọn ti imọ-ijinlẹ gẹgẹ bi awọn ero pupọ miiran.”23 Awọn eniyan onimọ nipa isọfunni tí ó ṣee gbarale ninu iran-eniyan kọọkan ti pari ero si pe Ẹni Akọkọ oloye kan, ẹlẹdaa kan nilati wà tí ô jẹ Ẹni Giga Julọ. Bibeli sọ nipa bi ọrọ naa ti rí loju wọn, nigba tí ó wipe: “Awọn ọrun nsọrọ ogo Ọlọrun; ati ofuurufu nfi iṣẹ ọwọ rẹ̀ hàn.” *
24 Yala o ti dé ori ipinnu naa pe Ọlọrun wà tabi bẹẹ kọ, ohun tí a ti ṣayẹwo rẹ̀ nipa iwalaaye, nipa ara awa tikaraawa, ati nipa agbaye yẹ ki ô ṣe iranlọwọ lati ṣalaye idi tí ọpọlọpọ awọn eniyan onironu fi ní ìdálójú-igbagbọ pe Ọlọrun kan wà. Eyiini sún wa lọ si ọran kan tí ô farapẹ́ eyiini: Bi Ẹlẹdaa naa bá wà, njẹ kò ha bọgbọnmu pe oun yoo ní ibasọrọpọ pẹlu awọn ẹda rẹ̀, tí yoo sì dahun awọn ibeere wa pe: Eeṣe tí a fi wà nihin? Eeṣe tí iwa-buruku fì wà lọpọ kaakiri? Kinni ohun tí ọjọ-ọla ní ní ipamọ? Bawo ni a ṣe lè rí ayọ?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 8 Job 33:4, New English Bible.
^ ìpínrọ̀ 18 Job 35:5, New English Bible.
[Koko Fun Ijiroro]
Eeṣe tí ó fi yẹ ki a gbà ọran naa yẹwo pe, ‘Njẹ Ọlọrun ha wà bi?’ (1-3)
Sí kinni ni iwalaaye lori ilẹ-aye tọkasi? (4-9)
Kinni ohun tí a lè kẹkọọ rẹ̀ nipa awọn cell wa tí ó ṣeranwọ nigba tí a bá nronu nipa wíwà Ọlọrun? (10-14)
Bawo ni ọpọlọ eniyan ṣe fi ẹri iṣeto hàn? (15-17)
Kinni ohun tí ô ṣamọna awọn eniyan pupọ lati pari ero si pe a ṣẹda agbaye lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun? (18-24)
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]
“Lonii, ó keretan ida 80 ninu ọgọrun lara awọn onimọ-ijinlẹ tí wọn nbojuto ọran ẹkọ nipa awọn ohun abẹ̀mí ni o ṣeeṣe pe ki wọn gbà pe ẹkọ nipa awọn ohun abẹmi ati iwalaaye ni a ṣe letoleto lati ọ̀dọ̀ agbara kan tí o ga julọ.
“Eto ati ilana tí ó galọla ninu awọn òkan-kò-jọkan ifarahan ohun abẹ̀mí ati ninu awọn itolẹsẹẹsẹ onipilẹ lori awọn idiwọn ti cell tí o kere julọ kọọkan ati idipọ wọn ní ipa ti ó lagbara lori igbagbọ naa pe agbara tí ó ga julọ kan wà.” – “Journal ’of the American Medical Association.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
ETO LATI IBO?
Dr. Paul Davies, olukọni ninu iṣiro iṣẹ-ẹrọ ní King’s College, London, kọ ninu New Scientist pe:
“Ibikibi yowu ki a gbé oju sí ní Agbaye, lati inu awọn ìṣùpọ̀ irawọ jínjìn-réré titi dé inu ọ̀gbun tí o jinlẹ julọ ti kúlẹ̀kúlẹ̀ atom (eyi tí ó kere julọ ninu awọn ohun-wíwà), a maa nṣe alabapade eto . . . Bi ó bá jẹ pe isọfunni ati eto bá maa nfi igba gbogbo ni itẹsi ti adánidá kan lati pòôrá, nibo ni gbogbo isọfunni tí ó mú ki ayé jẹ ibi akanṣe kan bẹẹ ti wá ní ipilẹṣẹ?”
Sir Bernard Lovell, ti Jodrell Bank Observatory olokiki ti England, kọwe pe awọn imọlara oun dabi ọ̀kan naa pẹlu awọn ti Albert Einstein:
“Iyanilẹnu alayọ nla niti iṣọkan ti ofin iṣẹda, tí o fi ọgbọn ti ò jẹ ti iru eyi ti ò galọla pupọ tobẹẹ hàn, tí ó si jẹ pe ní ifiwera pẹlu rẹ̀, gbogbo ironu oniṣisẹ-ntẹle ati igbesẹ awọn ẹda-eniyan jẹ ifarahan kan tí kò jámọ nkankan rara ati rara.”—Centre of lmmensities.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
AWỌN CELL RẸ
MITOCHONDRIA n mú awọn eroja jade lati mú agbara wá
NUCLEUS nṣe akoso gbogbo awọn igboke-gbodo inu cell
AWỌN IPA-ỌNA ISOKỌRA IṢẸ nkò awọn eroja wọ inu ati jade kuro ninu cell
RIBOSOMES nmú awọn protein jade ati awọn omi inu ẹjẹ fún ipinkiri si awọn ẹya-ara gbogbo
AWỌ FẸ́LẸ́FẸ́LẸ́ ati PROTEIN nṣakoso ohun ti ó bá wọle wá, ó si n gbogunti awọn agboguntini
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
ỌPỌLỌ ỌDỌBINRIN NAA
nmú ki ó—
Máradúró lori kẹ̀kẹ́ naa
Gbọ́ ìró ọkọ̀ tí nbọ̀
Gbóòórùn awọn òdòdó
Ní imọlara afẹfẹ
Ṣakiyesi ajá naa
Ranti ọna tí ó lọ si ile
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
TANI ẸNI TÍ Ó ṢIṢẸ-ỌNÀ ARA ẸDA-ENIYAN?
ỌPỌLỌ: Ó tayọ jinna-réré pupọ si computer kan, pẹlu agbara-àyè tí a ṣiro rẹ̀ si eyi tí ó fi ilọpo billion kan lọpo gbogbo ibi tí a lè lò ó dé lọ lasikko tí ẹda-eniyan fi walaaye.
OJU-IRIRAN: Ere ayaworan tí ndáṣiṣẹ funraarẹ̀ ninu yíyan ọgangan ìfojúsùn, eyi tí àwọ̀ aworan rẹ̀ tí nrìn kii ṣú bàìbàì.
ỌKÀN-ÀYÀ: Ẹrọ tí ntú nkan jade tí ó gbeṣẹ lọna giga ju ẹrọ eyikeyi tí eniyan tíì ṣe lọ. O ntú 1,500 jálá (5,700 L) tabi jù bẹẹ lọ jade ní ojoojumọ.
Ẹ̀DỌ̀-KI: ile-iṣẹ ayẹwo awọn ohun tí nfun ara lokun tí é jẹ ti pípo nkan pọ̀ tí ôó ní ju 500 awọn iṣẹ lọ. Ó nṣẹda iye awọn omi-ara amúṣẹ̀yá inu ara (enzyme) tí ó ju 1,000 lọ.
AWỌN EGUNGNU: Àgọ́ kan tí ó ní awọn apá pupọ tí ó tẹ̀wọ̀n kiki 20 oṣuwọn (9 kg), sibẹ tí ó lagbara gẹgẹ bi awọn irin nla tí a wépọ̀.
ETO-IṢIṢẸ IṢAN IMỌLARA: Eto ìsokọ́ra iṣẹ ibarasọrọpọ tí nrí iṣẹ gbà ati/tabi tí nṣiṣẹ lori awọn imọlara 100,000,000 ní iṣẹju àáyá kanṣoṣo.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Bawo ni agbaye pẹlu aimọye billion awọn ìṣupò irawọ ṣe wáyé?