Njẹ Igbesi-aye Alayọ kan Ha Ṣeeṣe Nitootọ Bi?
Orí 1
Njẹ Igbesi-aye Alayọ kan Ha Ṣeeṣe Nitootọ Bi?
“Ó DARA lati walaaye! bi imọlara eniyan ṣe nrí niyii nigba tí ó bá ní ayọ̀. Ṣugbọn bi a kò bá ni tan araawa jẹ, a mọ pe igbesi-aye kii maa fi igba gbogbo rí bẹẹ. Awọn ọran-iṣoro wà. Awọn wọnyi lè pọ̀ pupọ ati ki wọn sì wuwo tobẹẹ gẹ́ẹ́ tí ayọ̀ tootọ yoo kàn wulẹ dabi àlá kan lasan. O ha nilati rí bẹẹ bi?
2 Iwọ mọ̀ pe awọn ohun pupọ ni ó mú ki igbesi-aye kan jẹ alayọ. Lati gbadun igbesi-aye a nilo ohun tí ó pọ̀ to lati jẹ, ati aṣọ tí ó baramu. A nilo ile kan nibi tí a ti lè rí aabo ati isinmi. Sibẹ awọn wọnyi kàn wulẹ jẹ awọn nkan koṣeemani ni. Ibakẹgbẹpọ tí ó tunilara ati ilera daradara tún ṣe pataki pẹlu.
3 Ṣugbọn ani awọn wọnni tí wọn ní awọn nkan wọnyi dé àyè kan tún ṣì lè maa yánhànhàn fun ayọ̀ tootọ. Iru iṣẹ tí ẹnikan nṣe, tabi awọn ipo tí oun nilati ṣiṣẹ labẹ rẹ̀, lé mú un padanu itẹlọrun. Pẹlupẹlu, ninu awọn ọpọlọpọ idile ni iforigbari maa nwà laarin ọkọ ati iyawo tabi laarin awọn obi ati awọn ọmọ. Bẹẹ ni a kò lè gbojufo ṣiṣeeṣe aisan tabi iku ojiji tí ó rọdẹdẹ sori gbogbo wa. Iwọ ha gbagbọ pe ó ṣeeṣe lati koju awọn wọnyi ati awọn ọran-iṣoro miiran lọna kan tí yoo fi ṣeeṣe fun wa lati rí itẹlọrun tootọ bi? Idi wà lati gbagbọ bẹẹ. Sibẹ fun ẹnikan lati gbadun igbesi-aye alayọ, lakọkọ ná ó nilo ohun kan tí kii ṣe gbogbo eniyan ni wọn ní in—idi kan lati walaaye.
4 Igbesi-aye rẹ gbọdọ ní itumọ bi iwọ yoo bá jẹ alayọ nitootọ. Ninu iwe rẹ̀ The Transparent Self, Professor S. M. Jourard kọwe pe:
Eniyan kan yoo maa bá igbesi-aye lọ niwọn igba tí ó bá ṣì nní imọlara iriri naa pe igbesi-aye oun ní itumọ ati iniyelori ati titi dé igba tí ó bá ṣì ní ohun kan tí ó ngbé ayé fun ... Kete tí itumọ, iniyelori ati ireti bá ti lọ kuro ninu imọlara iriri eniyan kan, ó bẹrẹsi dáwọdúró lati walaaye; Ó bẹrẹsi kú.”
Ani eyi paapaa ni a ti ngbà pe ó rí bẹẹ ní ile-iṣẹ. Irohin kan lati Canada lori pípa ibi iṣẹ jẹ sọ pe:
Awọn eniyan. nwá itumọ ninu igbesi-aye wọn, wọn kò sì ní itẹlọrun mọ lati kàn wulẹ jẹ ohun-eelo kan lásán-làsàn tí kò ní orukọ kankan ninu eto ẹgbẹ-oun-ọgba.—Atlas World Press Review.
5 Eyi ṣeranwọ lati ṣalaye idi rẹ̀ tí pupọ ninu awọn ọlọrọ kò fi ní itẹlọrun gidi gan-an. Óò, bẹẹ ni, wọn njẹun, wọn nsùn, wọn ní idile kan tí wọn sì nṣe ajọpin diẹ ninu awọn faaji ati itura igbesi-aye. Ṣugbọn wọn lé ronu pe a lè sọ ohun kan naa yii nipa awọn ẹranko pupọ. Ohun pupọ sii ṣì nilati wà ninu igbesi-aye.
6 Bẹẹ ni ẹmi gigun kan lasan kii ṣe idahun naa. Ọpọlọpọ awọn agbalagba tí wọn lọjọ lori ni wọn mọ̀ lati inu iriri pe ẹmi gígùn kan laisi imọlara ti aṣeyọri tabi ti pe a jẹ́ ẹni tí a nfẹ́ jẹ eyi tí nkó àárẹ̀ bani. Iwọ ha ti rí eyiini bi?
7 Aini idi kan tí nsunni lati walaaye ni a kò fi mọ si kiki ọ̀dọ̀ awọn tí wọn lọjọ lori nikan. Iwadii kan tí Daito Bunka University ní Japan ṣe fihan pe, ninu 1,500 awọn ọmọ ile-ẹkọ giga, ipindọgba 50 lori ọgọrun awọn ọmọbinrin ati ipindọgba 34 lori ọgọrun awọn ọmọkunrin ni wọn ti ronu kan ìpara-ẹni rí. Eeṣe? Akọkọ ninu awọn idi tí wọn sọ ni ainitumọ igbesi-aye. Ò ha yatọ pupọ bi ní Europe, ní America ati ní Africa? Igasoke jakejado ayé ninu ìpara-ẹni fihan pe
ọpọ julọ ninu awọn eniyan pupọ sii ni wọn jẹ alailayọ tí igbesi-aye wọn si ti sú wọn.8 Awa tikaraawa lè má ronu lọna tí ó buru jáì tó bayii. A lè rí i pe ayọ̀ diẹ ṣì ṣeeṣe laika awọn ọran-iṣoro sí. Sibẹ, a kò lè yebọ kuro ninu bibeere pe, Njẹ igbesi-aye ha ní itumọ gidi gan-an bi? Bawo ni mo ṣe lè ní ayọ̀ tí ó wà pẹtiti?
9 Ọgọrọọrun ọdun sẹhin ọba kan ronu lori pupọ ninu awọn ilepa igbesi-aye—níní idile kan, jijere ọrọ̀, mímú ki ẹkọ ẹni dara sii, gbigbadun àdídùn ounjẹ ati kíkọ́ awọn ile tí wọn jẹ oju ní gbẹ̀sẹ̀. Iru awọn nkan bawọnni lè dabi eyi tí ó mú faaji dání. Sibẹ ó tún wá ríi pe wọn tún lè mú ibinujẹ pupọ wá. Ó beere pe:
Nitori pe kinni eniyan ní ninu gbogbo laalaa ati aapọn rẹ̀ tí ó fi nṣe laalaa labẹ oòrùn? Nitori pe ọjọ rẹ̀ gbogbo, ìkáàánú ni, ati iṣẹ rẹ̀, ibinujẹ; nitootọ àyà rẹ̀ kò sinmi ní òru. Eyi pẹlu asán ni. *
10 A fi asán tí ó wà ninu rẹ̀ hàn gbangba lẹhin naa nigba tí á ṣapejuwe ohun tí ó duro de ẹnikan lẹhin awọn ọdun igbesi-aye tí kò pọ̀ lọ titi kan—oju tí kò riran daradara mọ, awọn apá ati ẹsẹ tí wọn ti di alailera, *
awọn ehín tí wọn ti jẹrà tabi ti wọn ti yọ dànù, oorun tí a kò sùn gbadun dé ọkàn ati ní paripari rẹ̀ iku.11 Nitori naa, ani ká tilẹ lè sọ pe a ní imọlara pe ayọ̀ wà tí a lè rí ninu igbesi-aye, awọn ibeere tí irúnilójú tún wà tí wọn kan gbogbo wa. Paapaa julọ ni ó rí bẹẹ nisinsinyi. Eeṣe? Ó dara, Vermont Royster akọwe oniwe-irohin ṣalaye pe ní eyi tí ó wulẹ fi diẹ ju 50 ọdun lọ awọn eniyan ti fikun imọ wọn ati agbara iṣiṣẹ wọn lọna kan tí ó gadabu, ṣugbọn lẹhin naa ó fikun un pe:
“Ohun, kan niyii tí ó jẹ kayefi. Ní rironu nipa eniyan tikaraarẹ, niti awọn ipo tí ó há sinu rẹ̀, niti ipo rẹ̀ ni agbaye yii, diẹ kekere bayii ni a ṣì fi sún siwaju ju akoko tí igba bẹrẹ lọ.Awọn ibeere naa ṣì wà niti ẹni tí a jẹ́ ati idi tí a fi jẹ́ bẹẹ ati ibi tí a nrè.”—Science Digest.
12 Amọ ṣa o, ẹnikan lè gbiyanju lati gbojufo awọn ibeere bawọnni dá ki ó si ‘gbadun igbesi-aye.’ Pupọ awọn nkan nì a lè sọ nipa iriri itẹlọrun ninu igbesi-aye laika awọn ọran-iṣoro rẹ̀ sí. Ṣugbọn kò yẹ ki a tan ara wa jẹ lati maa gbé igbesi-aye kan tí kò rí bẹẹ ṣugbọn tí a mọ-ọn-mọ wulẹ gbagbọ pe ó rí bẹẹ. * Igbesi-aye wa yoo ni itumọ gidi gan-an ati ipilẹ fun ayọ bi a bá bẹrẹsi loye, ẹni tí a jẹ́ ati idi tí a fi jẹ́ bẹẹ ati ibi tí a nrè. A ha lè ṣe eyiini bi?
13 Awọn onironujinlẹ ti maa nfi ìgba gbogbo pari
ero si pe awọn idahun naa sinmi lori ibeere pataki naa, ‘Ọlọrun ha wà bi?’ Bi Ọlọrun kan bá wà, ó bọgbọnmu pe oun yoo mọ ibi tí a ti wá, idi tí a fi wà nihin ati ibì tí a nrẹ̀. Oun yoo tún mọ idi rẹ̀ tí iwa ibi fi wà, boya yoo dopin, ati pe, bi yoo bá rí bẹẹ, lọna wo. Ati pe oun yoo mọ ohun tí a lè ṣe lati mú ki igbesi-aye wa tún layọ sii ati ki ó sì tún ní itumọ ninu sii. Nigba naa, a lè beere pe, ‘Ọlọrun ha wà bi?’[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 9 Oniwaasu 2:22, 23, ninu Bibeli.
^ ìpínrọ̀ 12 Fiwe Oniwaasu 7:2-6.
[Koko Fun Ijiroro]
Kinni ohun tí a nílò ki a tó lè ní ayọ̀ ninu igbesi-aye? (1-10)
Awọn ibeere wo ni a dojukọ nipa igbesi-aye, ati pe bawo ni igbagbọ ninu Ọlọrun ṣe wemọ ọn? (11-13)
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
‘IGBESI-AYE HA YẸ FUN GBÍGBÉ BI?’
Michele, obinrin ara France kan, sọ pe oun sá kuro nílé ati kuro ni adugbo “lati lè sà asala kuro lọwọ ayé alagabagebe ati kuro ninu ijakulẹ lati ọ̀dọ̀ awọn tí wọn yí mi ká.” Lẹhin naa—“Mo ṣe alabapade iwa pálapàla, lilo oògùn ní ilokulo ati awọn alabakẹgbẹpọ elewu. Awọn ọlọpaa adugbo ati ti agbaye nlé mi kiri. Diẹ lo kù ki emi bọ́ sọwọ awọn olòwò ẹrú alawọ funfun. Ní rinrin irin-ajo lati ibikan dé omiran ní wíwá alaye kan fun wíwà tí a wà nihin, mo dé ọ̀dọ̀ awọn ọpọlọpọ ẹya-isin. Ṣugbọn igbesi-aye kò dabi eyi tí ó niyelori tò lati maa gbé. Mo ní imọlara jíjẹ alaiwulo tí gbogbo ironu mi kò ju pe ki emi kú lọ.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]
ỌKUNRIN TÍ IPAYA MÚ
Ọkunrin kan ní Japan ti orukọ rẹ̀ njẹ Yamamoto sọ pe:
“Nigba tí mo nṣe imurasilẹ fun idanwo abawọle ile-ẹkọ giga ní awọn ọdun diẹ sẹhin, mo lo akoko tí o pọ̀ julọ ninu akoko mi lori rironu lori itumọ ati ete igbesi-aye. Bi mo ṣe ntẹramọ kikẹkọọ awọn iwe lori ẹkọ imọ-ọran ayé tó, bẹẹ ni ijakulẹ mi fi tubọ npọ̀ sii. Lẹhin tí mo yege ninu idanwo mi tán mo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu kan. Ṣugbọn ní rírí gbogbo awọn iwa ibi tí ó wà yí mi ká, mo tún dojukọ ibeere naa lẹẹkan sii pe, ‘Kinni ete igbesi-aye?’”
Oun kò rí awọn idahun tí ntẹnilọrun ninu awọn ẹkọ imọ-ọran awọn eniyan, awọn tí ó ti hàn kedere pe wọn ti kuna lati yanju awọn ọran-iṣoro araye. Bẹẹ ni ẹkọ tí ó kọ nipa ọrọ-itan tabi iriri rẹ̀ nipa iṣelu kò fihan pe akoso ẹda-eniyan eyikeyi ní idahun naa lọwọ. Awọn eniyan ti gbiyanju oriṣiriṣi awọn akoso, sibẹ ibeere tí ó niiṣe pẹlu itumọ igbesi-aye ṣì wà nibẹ. Ọkunrin ara Japan naa fikun un bayii pe:
“Mo bẹrẹsi gbé igbesi-aye tí nwá faaji kiri, tí mo si nṣe bẹẹ lati inu ibinujẹ ọkàn. Ṣugbọn kò pẹ̀ lọ titi ki emi tò rí iwa wèrè ti ó wà ninu eyiini. Nigbẹhin mo wá pari ero si pe idahun si ibeere ti ó ti nmú idaamu bá mi niti idi tabi ete igbesi-aye sinmi lori yala Ọlọrun wà tabi kò sí.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]