Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Opin Ayé” Ha Ti Sunmọle Bi?

“Opin Ayé” Ha Ti Sunmọle Bi?

ORI 15

“Opin Ayé” Ha Ti Sunmọle Bi?

IWỌ Ha Ti Muratan fun “Opin Aye Bi?” ni iwe-irohin Star ti Toronto beere. Ibeere yẹn yoo mú ki awọn eniyan kan ronu nipa awọn irohin, ọ̀kan bi iru eyi:

“Sydney, Australia—Ninu igbó ilẹ Australia, ọgọrun awọn olugbe ilu-nla tí wọn ti sá kuro ninu ile tí wọn sì ti kọ awọn ohun faaji igbesi-aye ode-oni silẹ ni wọn nmurasilẹ fun ohun tí wọn gbagbọ pe ó jẹ ’opin ayé’ tí ó kù si dẹdẹ.”

2 Sibẹ ọpọlọpọ awọn eniyan lonii ni wọn ndaamu pe “opin naa” lè dé niti gidi lati inu ogun agba onina atomik, ibajẹ ayika tabi awọn ewu gidi miran. Fun apẹẹrẹ:

“Akọwe imọ-ijinlẹ naa Isaac Asimov ti ka awọn oriṣi 20 ọna nipasẹ eyi tí iwalaaye fi lè di ìkékúrò lori ilẹ-aye, bẹrẹ lati ori iku oòrùn titi dé ori ìyàn.”—Iwe-irohin Star ti Toronto.

3 Bi ó tilẹ rí bẹẹ, a ní idi tí ó tubọ lagbara gidigidi jù bẹẹ lọ fun ìdàníyàn tí a gbeka ori Ọrọ Ọlọrun tí ó ṣee fọkàntẹ̀. Ọpọlọpọ ti kà ninu Bibeli nipa “opin ayé.” (Matthew 13:39, 40; 24:3) Ní mímọ̀ pe ohunkohun tí Ọlọrun bá ṣeleri yoo ṣẹlẹ, ó yẹ ki a fẹ lati rí ohun tí Bibeli wi nipa eyi ati bi ó ṣe lè kan iwalaaye wa nisinsinyi ati ní ọjọ-iwaju.

OPIN KAN—TI KINNI, NIGBA WO SÌ NI?

4 Iwe-mimọ mú un dá wa loju pe Ọlọrun yoo ké awọn wọnni tí nmú ki iwa-ibi ati ijiya pọ̀ sii kuro. (Psalm 37:28; 145:20) Jesu Kristi ati apostle Peter fi imuṣẹ idajọ tí nbọ̀ yii wé iparun aláṣàyàn, ti awọn eniyan tí Ọlọrun mú ki ó ṣẹlẹ ní akoko Noah. A kò pa ilẹ-aye funraarẹ̀ run. Ṣugbọn a fì ikun-omi tí ó bo gbogbo ayé mọlẹ pa awọn ẹni-buruku run. Ọlọrun dá Noah ati idile rẹ̀ sí; wọn di ẹgbẹ eniyan olododo ti ori ilẹ-aye kan tí a fọ̀mọ́. Lẹhin titọka pada si eyiini, Ọlọrun misi Peter lati sọ asọtẹlẹ dídé “ọjọ idajọ ati iparun awọn alaiwa-bi-Ọlọrun.” Eyiini ni “awọn ọrun titun ati ayé titun” yoo tẹle ninu eyi tí ’ododo yoo maa gbé. —2 Peter 3:5-7, 13; Oniwaasu 1:4; Isaiah 45:18.

5 Lọna ti ẹda, awa fẹ lati mọ igba tí opin oniparun eto-igbekalẹ awọn nkan isinsinyi yoo dé. Jesu sọ pe kiki Baba nikan ni ó mọ ’ọjọ ati wakati yẹn.’ (Matthew 24:36) Ṣugbọn eyiini ha fi wa sinu okunkun patapata bi? Bẹẹ kọ, nitori Ọlọrun fi pẹlu inuure fi isọfunni naa sinu Ọrọ rẹ̀ ki awọn olusin rẹ̀ baa lè mọ̀ nigba tí akoko naa bá sunmọ tosi.—Fiwe Amos 3:7.

6 Bibeli fun wa ní idi fun ìgbọ́kànlé ninu agbara iṣe Ọlọrun lati wòyesọtẹlẹ nipa awọn idagbasoke ọjọ-iwaju. Fun apẹẹrẹ, ninu Daniel 9:24-27 oun ṣe akọsilẹ asọtẹlẹ kan lati tọkafihan akoko naa tí Messiah, tabi Kristi, yoo dé. Luke oniṣegun ọrundun kìnínní naa sọ pe ní 29 C.E., awọn Jew, ní mímọ̀ nipa asọtẹlẹ Daniel, nduro de Messiah. (Luke 3:1, 2, 15) Abba Hillel Silver ọmọwe Jew fohunṣọkan pẹlu eyi, ní kikọwe pe: “A fojusọna fun Messiah ní nkan bii apá keji idamẹrin ọrundun kìn-ín-ní C.E.” A ri Jesu bọmi ó si di Kristi naa ní 29 C.E., ọdun naa gan-an tí asọtẹlẹ Daniel tọkafihan.

7 Asọtẹlẹ Daniel kan naa yii sọtẹlẹ pe lẹhin iku Messiah, ilu nla naa ati ibi mímọ ni a o parun. Bẹẹ ni, Ọlọrun sọ ọ ṣaaju pe a o pa Jerusalem ati temple mímọ rẹ̀ run, tí o sì fi opin si eto-igbekalẹ awọn nkan Jew tí ó wà nigba naa.—Daniel 9:26.

8 Kete ṣaaju iku rẹ̀ ní 33 C.E., Jesu ṣe imugbooro eyi. Ó sọ pe Ọlọrun ti npa Jerusalem ati temple rẹ̀ tì. Ó tún sọ pẹlu pe oun nlọ, lati pada wá lẹhin naa. (Matthew 23:37-24:2) Ṣugbọn awọn ọmọlẹhin rẹ̀ beere pe:

“Sọ fun wa, nígba wo ni nkan wọnyi yoo ṣẹ? Kinni oo ṣe amí [wiwanihin] rẹ ati ti opin ayé (tabi, ’eto-igbekalẹ awọn nkan?”—Matthew 24:3.

9 Ijẹpataki idahun rẹ̀ yoo jẹ ìyé tabi iku fun awọn Kristian ọrundun kìn-ín-ní. Bakan naa gan-an ni ó ti ṣe pataki fun wa, nitori pe, bi awa yoo ti ríi, èsì Jesu ní itumọ tí ó rekọja ohun tí awọn apostle beere nipa rẹ̀ tabi tí wọn lè loye rẹ̀.—John 16:4, 12, 13.

10 Jesu tọkasi asọtẹlẹ Daniel. (Matthew 24:15) Eyiini kò tíì figi dó ọdun naa fun isọdahoro Jerusalem, bẹẹ ni Jesu ki yoo ṣe bẹẹ. Ṣugbọn oun ṣapejuwe awọn iṣẹlẹ tí yoo gbarajọpọ di “ami” pe eto-igbekalẹ awọn Jew ti wà ninu awọn ọjọ ikẹhin rẹ̀. Iwọ lè ka awọn ọrọ rẹ̀ ninu Matthew 24:4-21 ati Luke 21:10-24. Oun sọtẹlẹ nipa awọn eke Messiah (Kristi), awọn ogun, àìtó ounjẹ, ìsẹ̀lẹ̀, ajakalẹ-arun, inunibini si awọn Kristian ati igbetaasi iwaasu gbigbooro. Ọrọ-itan jẹrii sii pe awọn nkan wọnni ṣẹlẹ laarin iran-eniyan naa tí ó laaja titi di igba tí awọn ara Rome fi pa Jerusalem run ní 70 C.E.

AWỌN EKE KRISTI: Josephus, opitan ọrundun kìnín-ní, mẹnukan awọn Messiah alafẹnujẹ mẹta

AWỌN OGUN: Awọn ogun Parthia wà ní iha apá osi iwọ-oorun Asia, awọn iditẹ ní Gaul ati Spain; awọn ariwo-rúdurùdu awọn Jew ní awọn apá Ilẹ-ọba naa; awọn ariwo-rúdurùdu awọn ara Syria ati awọn ara Samaria lodisi awọn Jew

ÌYÀN: Awọn ìyàn ṣẹlẹ ní Rome, Greece ati Judea, ọ̀kan ninu awọn tí a rohin nipa rẹ̀ ninu Iṣe 11:28

AWỌN ÌṢẸ́LẸ́: Iwọnyi ṣẹlẹ ní Crete, ní Smyrna, Hierapolis, Colossae, Chios, Miletus, Samos, Rome ati Judea

A ṢE INUNIBINI SI AWỌN KRISTIAN ṣugbọn wọn WAASU LỌNA GBIGBOORO: Wo akọsilẹ naa ninu Iṣe 8:1, 14; 9:1, 2; 24:5; 28:22

11 Nitori pe awọn Kristian ní igbẹkẹle ninu asọtẹlẹ Jesu wọn lè gbé igbesẹ agbẹ̀mílà. Kristi ti ṣe kilọ-kilọ: ‘Nigba tí ẹyin bá sì ríi tí awọn ọmọ-ogun adótini bá yí Jerusalem ká, ẹ sá.’ (Luke 21:20-24) Bi a ti sọtẹlẹ, awọn ara Rome labẹ Ọgagun Agba Gallus yí Jerusalem ká ní October 66 C.E. Bawo ni awọn Kristian ṣe lè sá? Lairotẹlẹ awọn ọmọ-ogun naa kángárá wọn lọ. Awọn Kristian, ní ṣiṣiṣẹ lori ikilọ Jesu, sá kuro ní ilu-nla naa. Ní 70 C.E., awọn ara Rome labẹ Ọgagun Agba Titus pada. Wọn sọ ilu-nla naa di ahoro, tí wọn sì pa eyi tí ó lé ní aadọta ọkẹ awọn Jew. Bi iwọ bá ṣe ibẹwo si Rome, o lè rí ohun-iranti eyi tí a gbé sori Ọwọn Bìrìkìtì Titus (Arch of Titus).

12 Ohun ti ó ṣẹlẹ laarin awọn ọjọ ikẹhin eto-igbekalẹ awọn nkan Jew fi ẹri ṣiṣee gbẹkẹle latokedelẹ “ami” tí Jesu fi funni. Eyi ṣe pataki fun wa nitoripe asọtẹlẹ Jesu nipa ’opin eto-igbekalẹ awọn nkan’ tilẹ tún ní itumọ titobi jù lonii.

IMUṢẸ MIIRAN TI ASỌTẸLẸ JESU

13 Ohun tí Jesu sọtẹlẹ nipa awọn eke Kristi, awọn ogun, ìyàn awọn ìsẹ̀lẹ̀, ati inunibini sí awọn Kristian rí imuṣẹ ṣaaju 70 C.E. Bi o ti wu ki o rì, oun woyesọtẹlẹ awọn ohun miiran tí ó ṣe kedere pe wọn nilati wáyé ní akoko kan lẹhin naa. Oun sọ pe “gbogbo ẹya ayé” ni a o fi ipá mú lati mọ wiwanihin rẹ̀ ninu ogo ti ọrun ní àmọ̀dunjú. (Matthew 24:30) Ati pẹlu, oun sọtẹlẹ pe a o ya awọn eniyan sọtọ gẹgẹ bi “agutan kuro ninu ewurẹ,” ati pe awọn eniyan ẹni bii agutan yoo wọle sinu ìyè ainipẹkun. (Matthew 25:32, 46) Awọn nkan wọnni kò ṣẹlẹ ṣaaju tabi ní 70 C.E.

14 Ní eyi tí ó ju 25 ọdun lọ lẹhin iṣubu Jerusalem, Ọlọrun sún apostle John lati kọwe ninu Iṣipaya nipa awọn iṣẹlẹ ọjọ-iwaju. Ninu ori kẹfa, John rí àrítélẹ̀ “awọn ọkunrin ẹlẹṣin” tí wọn yoo mú awọn ohun apanirun wá sori ilẹ-aye. Ninu kika Iṣipaya 6:3-8 iwọ yoo ríi pe John sọ asọtẹlẹ (1) ogun jíjà, (2) “àìtó ounjẹ”? ati (3) “arun aṣekupani.” Iwọnyi jẹ diẹ lara awọn ohun tí Jesu sọtẹlẹ ninu “ami” naa. Nipa bayii a ní afikun ẹri pe imuṣẹ ẹlẹẹkeji tabi eyi tí ó gbooro jù nipa awọn ohun tí Jesu ti sọtẹlẹ yoo wà. Professor A. T. Robertson sọ lori eyì pe:

“Ó pọ̀ tò fun ete wa lati ronu nipa Jesu bi ẹni tí nlo iparun temple ati ti Jerusalem eyi tí ó ṣẹlẹ ninu iran-eniyan naa ní A.D. 70, pẹlu gẹgẹ bi ami-apẹẹrẹ kan nipa ipadabọ lẹẹkeji ti oun funraarẹ̀ ati ti opin ayé tabi àṣekágbá sanmanni.”—Word Pictures in the New Testament, Idipọ Kìn-ín-ní, oju-ewe 188.

15 Ṣugbọn, ni awọn kan wi, nigba gbogbo ni awọn ogun, ìyàn ati awọn ajakalẹ-arun ti maa nwà. Nitori naa bawo ni ẹnikan yoo ṣe mọ imuṣẹ ẹlẹẹkeji “ami” naa yatọ?

16 Dajudaju, yoo nilati jẹ ohun kan tí ó hàn gbangba-gbàngbà, tí ó yatọ sí awọn ogun abẹle, ajakalẹ-arun àdájà tabi ìṣẹ̀lẹ̀ kanṣoṣo péré. Ṣakiyesi pe Iṣipaya 6:4 sọ pe ogun jíjà naa yoo “gba alaafia [kii ṣe kuro ní orilẹ-ede kan tabi ẹkùn-ipinlẹ kan, ṣugbọn] kuro lori ilẹ-aye.” Ní afikun, Jesu fihan pe yoo jẹ ami alápá-pupọ. Nitori naa, ní ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu ogun tí ó gbodekan, awọn ìyàn tí wọn gba afiyesi yoo wà, awọn ìsẹ̀lẹ̀ ati awọn arun, ní didarukọ diẹ péré. Gbogbo iwọnyi yoo wá sori iran-eniyan kanṣoṣo. (Matthew 24:32-34) Ní mimọriri eyi, ati ní bibojuwo ọrọ-itan ẹda-eniyan, ọpọlọpọ awọn eniyan nwòyemọ̀ ní kedere pe ’ami ipari-opin eto-igbekalẹ awọn nkan’ ti faráhan nisinsinyi.

“AMI” NAA NÍ AKOKO TIWA

17 Iṣipaya 6:4 fihan pe ogun jakejado ayé yoo wà. Ó ha ti wà bi? Bẹẹ ni, bẹrẹ pẹ́lu ogun 1914-1918. Onkọwe iwe-irohin Sydney J. Harris kọwe pe ’Ogun Agbaye Kìn-ín-ní kan awọn orilẹ-ede tí iye wọn ju ìpín 90 ninu ọgọrun gbogbo olugbe ayé.’ Ní ibamu pẹlu ohun tí Encyclopedia. Americana, wi, eyi tí ó ju 8,000,000 awọn ọmọ-ogun ni a pa ninu Ogun Agbaye Kìn-ín-ní tí eyi tí ó ju 12,000,000 awọn ara ilu sì kú nipasẹ ipakupa, ifebipaku ati ifarakanra pẹlu eroja oloro.

18 Awọn kan gbiyanju lati pa eyi tì sapakan nipa sisọ pe tẹlẹ ní iṣaaju awọn eniyan kò kàn ṣáà ní ohun-irinna ati imọ-ẹrọ fun ogun agbaye. Ṣugbọn eyiini tẹnumọ jíjẹ alailẹgbẹ Ogun Agbaye Kìn-ín-ní.

“Bi akoko ti nrekọja lọ lati awọn ọjọ August 1914, ó ti tubọ wá ṣe kedere siwaju sii pe ìbẹ́sílẹ̀ Ogun Agbaye Kìn-ín-ní tumọsi opin sanmanni kan.”—The Norton History of Modern, Europe.

“Ogun Agbaye Kìn-ín-ní—lọna rirọrun Ogun Nla Naa fun awọn olulaaja rẹ̀—ni ó ṣì jẹ koko pataki tí npín ọrọ itan ode-oni níyà ninu ero-inu awọn eniyan. . . . Otitọ kan wà ninu igbagbọ aláìmọ̀-ọn-mọ̀ gbà tí ọpọ julọ awọn eniyan dìmú pe awọn akoko ode-oni bẹrẹ pẹlu Ogun Agbaye Kìn-ín-ní. Eyi jẹ akoko naa nigba tí a padanu iwa-ọmọluwabi wa.”—Gazette ti Montreal.

“Ọdun 1918 kò mú ijọba ẹlẹgbẹrun ọdun wọle dé. Ó mú idaji ọrundun iforigbari wá—irukerudo, ogun, iditẹ, isọdahoro, ati iparun-bajẹ ní iwọn tí a kò rí iru rẹ̀ rí tabi ronuwoye nipa rẹ̀ rí.”—Professor H. S. Commager.

19 Bẹẹ ni, ’a mú ogun wọle dé niwọn tí a kò ronuwoye rẹ̀ rí,’ gan-an gẹgẹ bi Bibeli ti tọkafihan. Laipẹ ogun agbaye keji tún ṣẹlẹ tí ó mú laarin “35,000,000 si 60,000,000” iwalaaye lọ.

“Ogun Agbaye Keji ṣe itankalẹ iku ati isọdasan jakejado ibi pupọ julọ ninu ayé ní iwọn kan tí a kò rí iru rẹ̀ rí.... igbidanwo lati ṣalaye iye-owo dúkìá ati ohun ẹlẹmi tí a parun jásí òtúbántẹ̀, iye tí a ṣiro naa ga fiofio rekọja ààlà.”—Encyclopedia, Americana.

Iwọ sì mọ̀ pe yatọ si ọpọlọpọ awọn ogun lati 1945 wá, awa nisinsinyi ní ihalẹmọni ogun àgbá onina atomik.

20 Arun tí iru rẹ̀ kò ṣẹlẹ rí jẹ ẹri-ami miiran pe ìmuṣẹ pataki nipa “ami” naa bẹrẹ pẹlu Ogun Agbaye Kìn-ín-ní. (Luke 21:11) Lẹhin gbigba pe awọn arun iṣaaju pa iye gbigbooro laarin akoko awọn ẹwadun (decade) iwe-irohin naa Science Digest fi bi arun gágá ní 1918 ṣe gbooro tó hàn:

“Ogun naa ti pa eyi tí ó ju aadọta ọkẹ lọna mọkanlelogun eniyan laarin ọdun mẹrin tí ó kún fun iforigbari; ajakalẹ arun gágá mú nkan bii iye kan naa lọ laarin oṣu mẹrin. Ninu gbogbo ọrọ-itan kò tíì si ibẹwo iku tí ó lekoko, tí ó sì yara tó bayii rí. . . . Dokita kan pè é ní àjálù-ibi ti iṣegun jálẹ̀jálẹ̀ gbogbo akoko.”

“Iye numba tí gbogbo ayé nmẹniikan ni araadọta ọkẹ lọna mọkanlelogun awọn oku, ṣugbọn ó ṣeeṣe ki ó jẹ iṣiro àìpéye tí ó gadabu, iye yẹn pẹlu ni ó ti lè kú ní àgbáálá-ilẹ̀ India nikan; iku tí ó ṣẹlẹ nibẹ ní October 1918 ’jẹ alailafiwe ninu ọrọ-itan arun’ ”—Scientific American.

Bẹẹ naa ni awọn onimọ-ijinlẹ kò tíì dá ikore tí iku nṣe nipasẹ arun duro. Nigba tí ó bá dabi ẹnipe a “ṣẹgun” arun kan, omiran yoo yọju. Awọn eniyan fi awọn ọkọ ofuurufu ayára-bi-àṣá ranṣẹ sinu oṣupa, ṣugbọn, wọn kò tíì ṣẹ́pá arun malaria, cancer, ati aisan ọkàn-àyà.

21 Jesu sọ pe “awọn ìsẹ̀lẹ̀ ní ibi kan dé omiran” pẹlu yoo jẹ apakan “ami” naa. (Matthew 24:2; Luke 21:11) Awọn ìsẹ̀lẹ̀ ti wà jálẹ̀jálẹ̀ gbogbo ọrọ itan. Ṣugbọn bawo ni akoko naa laarin Ogun Agbaye Kìn-ín-ní ti rí ní ifiwera? Ninu II Piccolo, Geo Malagoli ṣakiyesi pe:

“Iran-eniyan tiwa ngbé ninu akoko elewu ti ìsẹ̀lẹ̀ titobi, gẹgẹ bi isọfunni-oniṣiro ti fihan. Nitootọ, laarin akoko tí ó jẹ 1,059 ọdun (lati 856 si 1914) awọn orisun tí wọn ṣee gbarale ṣe itolẹsẹẹsẹ 24 awọn ìsẹ̀lẹ̀ pataki tí wọn ṣokunfa 1,973,000 iku. Bi o ti wu ki o ri, (ninu) awọn jamba lọọlọọ, a ríi pe 1,600,000 eniyan ni wọn ti kú laarin kiki 63 ọdun péré, gẹgẹ bi abajade 43 ìsẹ̀lẹ̀ awọn tí wọn ṣẹlẹ laarin ọdun 1915 si 1978. Ibisi ojiji yii ntẹsiwaju lati tẹnumọ otitọ-iṣẹlẹ miiran tí a tẹwọgba—iran-eniyan tiwa jẹ olori buruku ní ọpọlọpọ ọna’’

22 Awọn eniyan lè sọ pe iye-eniyan ayé tí npọ̀ sii ati titobi awọn ilu-nla ni ó fa iye giga awọn tí wọn kú ninu ìsẹ̀lẹ̀ lati igba Ogun Agbaye Kìn-ín-ní. Ani bi eyi bá tilẹ jẹ idi naa, kò ṣe iyipada ninu ohun tí o ti ṣẹlẹ. Eyi pẹlu jẹ otitọ nipa ìyàn. Laika awọn itẹsiwaju ninu ipese ounjẹ si, iru bii Eto Bọ́ Ilu Yó, a nka isọfunni irohin bii iru awọn wọnyi:

“Ó keretan ọ̀kan ninu gbogbo eniyan mẹjọ lori ilẹ-aye ni aisan àìjẹun-re-kánú ṣì npọ́nlójú.”

“Ajọ Ounjẹ Agbaye ti U.N. padepọ ní Ottawa nigba ikore yii (ti 1980), ó sì fohunsii pe 50 million eniyan ni ebi npaku lọdọọdun.”

“Awọn ajọ tí nbojuto ọran ounjẹ lagbaye ṣiro pe eyi tí ó ju billion kan lọ lara awọn eniyan ni ki yoo ní ànító lati jẹ ninu ọdun yii.”

23 ‘’Ẹṣẹ yoo di pupọ” ati àjórẹ̀hìn ifẹ tún jẹ ẹri-ami pẹlu lati sami si ’ipari-opin eto-igbekalẹ awọn nkan.’ (Matthew 24:3, 12) Ó ṣeeṣe ki iwọ má nilo awọn isọfunni-oniṣiro lori iwa-ọdaran ati idayafoni lati lè fun ọ ní ìdálójú-igbagbọ pe eyi ti ní imuṣẹ lonii. Ṣugbọn, niti eyi, kà nipa apejuwe alasọtẹlẹ nipa “awọn ọjọ ikẹhin” ninu 2Timothy 3:1-5. Wo bi ó ti ṣedeedee ní ibaradọgba pẹlu ohun tí a dojukọ nisinsinyi.

KINNI Ó TUMỌ̇SI FUN Ọ?

24 Jesu sọtẹlẹ pe ọpọlọpọ eniyan ni hilahilo yoo débá nipa imuṣẹ “ami” naa. “Àyà awọn eniyan yoo maa já fun ibẹru ati fun ireti nkan wọnni tí nbọ sori ayé.? Bi o ti wu ki o ri, ó lè yatọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀. Kristi sọ fun wọn pe: “Ṣugbọn nigba tí nkan wọnyi bá bẹrẹsì ṣẹ, njẹ ki ẹ wo oke ki ẹ sì gbé ori yin soke; nitori idande yin kù si dẹdẹ.” (Luke 21:26, 28) Awa kò gbọdọ ṣaika ohun tí nṣẹlẹ yii sí, tabi ki a fi pẹlu iwa-omugọ rọ ọ tì sapakan gẹgẹ bi ohun àkọsẹ̀bá kan. Awọn wọnni tí wọn wà ní Jerusalem tí wọn ṣalaika imuṣẹ asọtẹlẹ Jesu ní ọjọ wọn sí padanu iwalaaye wọn. Jesu sọ fun wa pe: “Njẹ ki ẹ maa ṣọna . . .. ki ẹ baa lè la gbogbo nkan wọnyi tí nbọ̀ wá ṣẹ.”—Luke 21:34-36.

25 Bẹẹ ni, ó ṣeeṣe lati la opin eto-igbekalẹ awọn nkan buruku isinsinyi já. Kò sí ẹda-eniyan kankan tí ó mọ “ọjọ ati wakati” naa ní pato fun opin tí nbọ̀, ṣugbọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ lori ilẹ-aye ní akoko tiwa fi ẹri hàn pe ó ti sunmọle gírígírí. Bi o ti wu ki o ri, ohun tí a beere lọwọ wa ju kiki “ṣiṣọna” lọ. (Matthew 24:36-492) Ó nilati ní ipa lori ironu ati iwa wa. Peter kọwe pe: “Igbesi-aye yin gbọdọ jẹ mímọ́ ati eyi tí a yasimimọ fun Ọlọrun, bi ẹ ti nduro de Ọjọ Ọlọrun. . . . Ẹ sa gbogbo ipá yin lati lè jẹ ojulowo ati alailabuku.”—2 Peter 3:11-14, Good New Bible.

26 Gẹgẹ bi apakan “ami” naa, Jesu wipe: “A o si waasu ihinrere ijọba yii ní gbogbo ayé lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo sì dé.” (Matthew 24:14) Fun wa lati ní ipin ti ó bojumu ninu iṣẹ naa, a nilati mọ ohun tí “ijọba” naa nṣe ati idi tí ó fi ṣe pataki tobẹẹ nisinsinyi niwọn bi opin ti sunmọle. Ẹ jẹ ki a ṣayẹwo eyi nisinsinyi.

[Koko Fun Ijiroro]

Eeṣe tí ṣiṣe awọn nkan lọna ti Ọlọrun fi jẹ ọna didara julọ fun rírí ayọ̀? (1-3)

Eeṣe tí awa fi gbọdọ pinnu yala a fẹ́ lati jẹ ọ̀rẹ́ ayé tabi ti Ọlọrun? (4-6)

Ní ibamu pẹlu Bibeli, kinni yoo wá sí opin? (4)

Eeṣe tí a fi lè ní idaniloju pe “opin” naa yoo dé? (5, 6)

Kinni ohun tí Jesu wòye-sọtẹlẹ nipa eto-igbekalẹ awọn nkan Jew? Kinni ó sì ṣẹlẹ? (7-10)

Bawo ni ó ti ṣe pataki tó lati loye “ami” naa? (11, 12)

Eeṣe tí a fi nilati wọna fun imuṣẹ miiran ti “ami” naa, bawo ni yoo sì ṣe yatọ si imuṣẹ akọkọ? ( 13-16)

Bawo ni ogun jíjà tí a sọtẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ ní akoko tiwa? (17-19)

Imuṣẹ wo ni ó ti ṣẹlẹ niti ajakalẹ-arun? (20)

Ẹri miiran wo ni iwọ lè tọkasi, tí nfihan pe “ami? naa nní imuṣẹ? (21-23)

Ipa wo ni imuṣẹ lọọlọọ ti “ami” naa nní lori igbesi-aye rẹ? (24-26)

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 140]

“Awọn ìwòye-sọtẹlẹ nipa opin ayé ni a ti nsọ lati igba laelae. . . . Lonii, bi o ti wu ki o ri, awọn apẹẹrẹ-iyanu tí nfi ibi hàn ṣaaju wà tí wọn ki yoo parẹ; ’awọn ọran-iṣoro eniyan’ tí wọn dabi eyi tí kò ṣee yanju ani nipasẹ awọn ọjafafa oṣelu; awọn asinwín oṣelu oniwa-ẹhànnà ninu ayé alagbara atomik ati iparun bii ti ikán tí ẹda-eniyan nṣe sí ayika alailafirọpo rẹ̀.’’​—“The Spectator,” Ontario,Canada

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 147]

“Ogun kò tíì fi igba kankan rí rọrun lati tumọ boya Ogun Agbaye Kìn-ín-ní sì ni eyi ti ó lekoko julọ. Ní isalẹ awọn akọsilẹ awọn idije ati adehun ajumọṣe eyi tí awọn opitan lò lati ṣalaye ogun naa, nibẹ ni òye ohun kan tí ó tobi jù gbé wà, òye ainisinmi tí nyọ ayé lẹnu. . . .. ekukáká ni ogun naa fi pari ti ayé tún fi bẹrẹsi murasilẹ fun omiran.”—Barry Renfrew ti Associated Press.

“Awọn iṣẹlẹ tí a mú ki ó bẹrẹsi ṣẹlẹ ní August 4, 1914 ... pa eto iṣelu-oun-iwarere run kuro, ó ké ìmúbáradọgba agbara awọn orilẹ-ede kuro, ó fi opin si ipa ti Europe nkó gẹgẹ bi oludasilẹ awọn iṣẹlẹ ti o sì pa, bi ò ti nbá a lọ, awọn aimọye araadọta ọkẹ mejila-mejila eniyan. . . . ni 1914 ayé padanu isopọmọra kan eyi ti kò tíì lé gbiyanju lati mú padabọsipo lati igba naa.”—London, “The Economist.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 149]

AWỌ̇N IKU ÌSẸ̀LẸ̀ (A gbé iṣiro ka ori 1,122)

Titi dé 1914- 1,800 lọdun

Lati 1914 wá- 25,300 lọdun’’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 144]

Ní ṣíṣiṣẹ́ lórí Jesu, awọn Kristian sá kúrò ní Jerusalem ṣaaju kí awọn ara Rome tó pa á run