Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Rere Ha Wà ninu Gbogbo Isin Bi?

Rere Ha Wà ninu Gbogbo Isin Bi?

Ori 18

Rere Ha Wà ninu Gbogbo Isin Bi?

NIGBA tí a bá njiroro nipa isin, ọpọlọpọ eniyan nwipe, ’Rere wà ninu gbogbo isin,’ tabi, ’Gbogbo isin wulẹ jẹ oriṣiriṣi ọna tí nsinni lọ sọdọ Ọlọrun.’

2 Ó rọrun lati rí idi tí awọn eniyan lé fi rí awọn rere kan ninu eyi tí ó fẹrẹẹ jẹ isin eyikeyi, nitori pe pupọ julọ ninu wọn ni wọn nsọrọ nipa ifẹ tí wọn sì nkọni pe ìmọ̀-ọn-mọ̀ paniyan, ole jíjà ati irọ́ pípa kò tọna. Awọn ẹgbẹ onisin ti rán awọn onṣẹ-isin jade lati bojuto awọn ile-itọju-alaisan ki wọn sì ran awọn alaini lọwọ. Ati ní pataki ní awọn ọrundun meji tí ó kẹhin wọn ti ṣe alabapin ninu titumọ ati ipinkiri Bibeli, tí wọn nfi bẹẹ yọnda fun eniyan pupọ sii lati janfaani lati inu Ọrọ Ọlọrun. (2 Timothy 3:16) Sibẹ a jẹ ara wa ní gbèsè bibeere pe: Oju wo ni Jehofah ati Jesu Kristi fi nwo oriṣiriṣi awọn isin?

ỌNA Tí Ó TỌ̀—ỌNA TÓÓRÓ

3 Awọn eniyan kan tí wọn ní imọlara pe rere wà ninu gbogbo isin kà á sí ironu kukuru lati gbagbọ pe Ọlọrun ki yoo tẹwọgba pupọ julọ awọn eniyan ìru eyi yowu ki isin wọn jẹ. Ṣugbọn Jesu, ẹni tí ó mọ̀ tí ó sì nfi ironu Baba rẹ̀ hàn, ní oju-iwoye tí ó yatọ. (John 1:18; 8:28, 29) Kò sí ẹnikẹni ninu wa tí yoo fi pẹlu ọgbọn ka ẹsun níní ironu kukuru sí Ọmọkunrin Ọlọrun lọ́rùn. Ṣe ayẹwo ohun tí ó sọ ninu Iwaasu lori Oke:

Ẹ bá ẹnu-ọna, híhá, wọle; gbooro ni ẹnu-ọna naa, ati oníbùú, ni oju-ọna naa tí lọ sibi iparun; ọpọlọpọ ni awọn ẹni tí nbá, ibẹ wọle. Nitori hihá, ni ẹnu-ọna naa,, tóóró sì ni oju-ọna naa tí ó lọ sibi ìyè diẹ ni awọn, ẹni tí wọn, nri i—Matthew 7:13, 14.

4 Kinni ohun tí ó nbeere lati lè wà ní oju-ọna tóóró naa ki a sì ní itẹwọgba Ọlọrun? Awọn kan, ní ìlà pẹlu ẹmi kò-kò-kan ati iṣọkan-ṣọọṣi ti ode-oni, yoo dahun pe, ’Sá ti maa ṣe rere ki o sì yàgò fun pipa awọn ẹlomiran lara,’ tabi, ’Gbogbo ohun tí o nilo ni pe ki o gba Jesu gẹgẹ bi Oluwa rẹ.’ Ṣugbọn Jesu sọ pe pupọ sii ni ó ṣe pataki:

“Kii ṣe gbogbo ẹni tí npé mi ní Oluwa, Oluwa, ni yoo wọle ijọba ọrun; bikoṣe ẹni tí NṢE IFẸ TI BABA MI tí nbẹ ní ọrun. Ọpọlọpọ eniyan ni yoo wi fun mi ní ọjọ naa pe, ’Oluwa, Oluwa, . . . orukọ rẹ ki a fi ṣe ọpọ iṣẹ iyanu nla? Nigba naa ni emi yoo sì jẹwọ wi fun wọn pe, Emi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kuro lọdọ mi, ẹyin oniṣẹ ẹṣẹ.”—Matthew 7:21-23.

5 Otitọ ni pe Jesu gbani-nimọran lodisi ṣiṣe idajọ awọn arìwisì alailẹsẹnilẹ nipa awọn ẹlomiran. (Matthew 7:3-5; Rome 14:1-4) Ṣugbọn lori ọran pataki ti isin, oun fi ara rẹ̀ ṣe apẹẹrẹ aini naa lati rọ̀mọ́ Bibeli, ati lati ṣe ifẹ-inu Baba. Jesu dẹbi fun awọn iṣe-aṣa ati awọn ẹkọ tí wọn forigbari pẹlu Ọrọ Ọlọrun. Eeṣe? Nitori oun mọ̀ pe Eṣu nlo isin lati fi dẹkùn mú awọn eniyan. (2 Corinth 4:4) Irinṣẹ Satan ni eke-ṣiṣe, ṣugbọn ó ngbé e kalẹ lọna tí ó mú un fanimọra. (Genesis 3:4, 5; 1 Timothy 4:1-3) Ani laarin awọn tí wọn jẹwọ jíjẹ Kristian paapaa awọn aṣaaju isin wà tí wọn nṣiṣẹ-ṣeranwọ fun awọn ifẹ-ọkan Eṣu. (2 Corinth 11:13-15) Awọn ẹkọ wọn nṣoju lọna òdì fun awọn ọna onifẹẹ ati ọ̀làwọ Jehofah. Eyi ha jẹ kayefi kankan, nigba naa, pe Jesu tú aṣiri awọn aṣaaju isin tí awọn ẹkọ wọn wà ní ilodisi Iwe-mimọ bi?—Matthew 15:1-20; 23:1-38.

6 Ní sisọ ọ lọna ifiwera bẹẹ, ọpọlọpọ eniyan ni wọn ti jogun isin wọn. Awọn miiran wulẹ ntẹle ọpọlọpọ tí wọn wà ní ayika wọn lọ. Ṣugbọn bi eyi tilẹ jẹ pẹlu otitọ-inu paapaa, ó lè fi eniyan sí ’oju-ọna gbooro tí nsinni lọ si iparun.’ (John 16:2; Owe 16:25) Apostle Paul (tí orukọ rẹ̀ njẹ Saul pẹlu) ti jẹ onitara ninu isin rẹ̀ tẹlẹ ani titi dé ori ṣiṣe inunibini si awọn Kristian. Sibẹ lati di ẹni itẹwọgba fun Ọlọrun, oun nilati yipada si ọna ijọsin titun. (1 Timothy 1:12-16; Iṣe 8:1-3; 9:1, 2) Lẹhin naa, a misii lati kọwe pe awọn eniyan onifẹẹ isin kan nigba naa lọhun ní ’itara fun Ọlọrun, ṣugbọn kii ṣe gẹgẹ bi imọ pipeye.’ (Rome 10:2) Iwọ ha ní imọ pipeye nipa ifẹ-inu Ọlọrun tí a làsílẹ̀ ninu Bibeli bi? Iwọ ha nhuwa ní ibamu pẹlu eyi bi?

7 Maṣe fi ọwọ dẹngbẹrẹ mú eyi rara, boya ki o maa ní imọlara pe bi iwọ kò bá tilẹ sí ní oju-ọna títọ́ ní rẹgirẹgi ọran naa yoo yé Ọlọrun laijẹ pe iwọ yoo nilati ṣe awọn iyipada kankan. Iwe-mimọ ṣalaye pe ifẹ-inu Ọlọrun ni fun awọn eniyan lati “wá sinu imọ otitọ,” lẹhin naa ki wọn sì gbé ní ibamu pẹlu rẹ̀. (1 Timothy 2:3, 4; James 4:17) Ọlọrun sọtẹlẹ pe ní “awọn ọjọ ikẹhin” ọpọlọpọ eniyan ni yoo “ní afarawe iwa-bi-Ọlọrun ṣugbọn tí wọn sẹ́ agbara rẹ̀.” Oun paṣẹ pe: “Yẹra kuro lọdọ awọn wọnyi pẹlu.”—2 Timothy 3:1-5.

BAWO NI O ṢE LÈ MỌ?

8 Bi o tilẹ jẹ pe ijọsin tí ó wu Ọlọrun gbọdọ wà ní ibamu pẹlu ’imọ pipeye,’ ayẹwo fihan pe pupọ julọ awọn ṣọọṣi nkọni ní awọn ẹkọ isin tí wọn forigbari pẹlu Bibeli. (Rome 10:2) Fun apẹẹrẹ, wọn di ẹkọ tí kò bá iwe-mimọ mu naa mú sibẹ pe eniyan ní aileeku ọkàn. (Ezekiel 18:4, 20, wo oju-ewe 115.) ’Ẹkọ naa ha buru tobẹẹ bi?’ ni awọn kan lè ṣe kayefi. Maṣe gbagbe pe irọ́ akọkọ tí Satan pa ni pe ẹṣẹ ki yoo mú iku wá. (Genesis 3:1-4) Ní bayii tí iku jẹ alaiṣee yẹsilẹ, ẹkọ naa pe eniyan ní ọkàn aileeku ní itẹsi mímú ki irọ́ Satan tẹsiwaju. Ó ti sún araadọta ọkẹ awọn eniyan sinu ibaṣepọ onibẹru pẹlu awọn ẹmi-eṣu tí wọn ngbé agọ̀ wọ̀ bi ọkàn awọn oku. Ẹkọ-isin naa sì mú ki otitọ Bibeli naa nipa ajinde awọn oku tí nbọ̀ jẹ alainitumọ.—Iṣe 24:15.

9 Iwa pẹlu tún wà ninu rẹ̀, nitori pe ọpọlọpọ isin ni wọn tẹwọgba tabi kọwọti awọn ọjọ isinmi akiyesi (holiday) ati awọn aṣa tí a gbeka ori igbagbọ ninu aileeku ọkàn. Halloween, Ọjọ Gbogbo Ọkàn ati awọn miiran jẹ iru awọn ọjọ isinmi akiyesi bẹẹ, tí nṣàdàlù awọn iṣe-aṣa tí a mú wá lati inu awọn isin tí kii ṣe Kristian.

10 Ṣiṣe amulumala awọn isin tí kii ṣe Kristian ati awọn tí a lérò pe wọn jẹ Kristian tún nasẹ dé ori awọn ọjọ isinmi akiyesi miiran, iru bii Keresimesi. Ọlọrun dari awọn Kristian lati ṣe iranti iku Jesu, kii ṣe ìbí rẹ̀. (1 Corinth 11:24-26) Bibeli sì fihan pe a kò bí Jesu ní December, tí ó jẹ́ akoko òjò olotutu ní Israel. (Luke 2:8-11) Iwọ lè yẹ encylopedia eyikeyi wò ki o sì ríi pe wọn yan December 25 nitori pe ó ti jẹ ọjọ isinmi akiyesi kan fun awọn ara Rome tẹlẹriì. Sir James Frazer ṣakiyesi pe:

“Ki a kó gbogbo rẹ̀ papọ, ṣiṣe kongẹ (Keresimesi ati Easter) pẹlu awọn ajọdun abọriṣa ti sunmọra pẹkipẹki julọ ó sì pọ̀ kọja jíjẹ èèṣì lasan. . ... (Awọn alufaa) wòye pe bi isin Kristian yoo bá bori ayé yoo lè ṣe bẹẹ kiki nipa didẹwọ awọn ilana-ipilẹ lilekoko ti Oludasilẹ rẹ̀, nipa mímú ki ọna tóóró naa tí ó lọ sí igbala tubọ fẹ̀ diẹ sii.”—The Golden Bough.

11 Lẹhin tí oun ti kẹkọọ awọn otitọ-iṣẹlẹ, eniyan wo tí ó fẹran Jehofah pẹlu otitọ-inu ni yoo maa bá a lọ lati tẹwọgba awọn igbagbọ ati iṣe-aṣa tí a gbeka ori ifibọpo-bọyọ pẹlu ijọsin keferi? Fun awọn eniyan awọn ẹkọ tabi iṣe-aṣa wọnyi lè dabi ohun kekere kan lasan. Ṣugbọn Bibeli sọ gbangba pe: “Iwukara kínún ni nsọ gbogbo iyẹfun di wíwú.”—Galatia 5:9.

OGUN ATI IWARERE

12 Jesu Kristi tún ṣe ìlàsílẹ̀ iranlọwọ miiran ní mímọ isin tí ó ṣe itẹwọgba fun Jehofah nigba tí ó sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pe: “Nipa eyi ni gbogbo eniyan yoo fi mọ pe, ọmọ-ẹhin mi ni ẹyin iṣe, nigba tí ẹyin bá ní ifẹ si ọmọnikeji yin.” (John 13:34, 35) Pupọ julọ awọn ṣọọṣi ni wọn nsọrọ nipa fifi ifẹ hàn, ṣugbọn nitootọ ni wọn ha nrọni lati fi iru ifẹ tí Jesu ní hàn bi?

13 A ti ríi pe awọn Kristian ní awọn ọrundun ijimiji gbé ní ibamu pẹlu apejuwe alasọtẹlẹ tí ó wà ninu Isaiah 2:4. Wọn ’fi idà wọn rọ ohun-elo itulẹ wọn kò sì gbé idà soke si ara wọn bẹẹ ni wọn kò kọ́ ogun jíjà.’ (Wo oju-ewe 166, 167.) Ipo wo ni awọn ṣọọṣi ati awọn alufaa wọn ti dìmú? Ọpọlọpọ eniyan ló mọ̀ lati inu iriri ara-ẹni tiwọn pe awọn ṣọọṣi tẹwọgba tí wọn sì ti sure fun ogun jíjà—onisin Catholic npa onisin Catholic, onisin Protestant npa onisin Protestant. Eyi dajudaju kii ṣe titẹle ipa-ọna tí Jesu fi lelẹ. Lọna tí ó gba afiyesi, awọn aṣaaju isin Jew ni awọn ẹni tí, ní sisọ pe awọn ire orilẹ-ede naa wà ninu ipo aidaniloju, wọn fọwọsi pipa Jesu.—John 11:47-50; 15:17-19; 18:36.

14 Gẹgẹ bi iranlọwọ siwaju sii ní pipinnu yala ẹgbẹ isin kan ní itẹwọgba Ọlọrun, ṣe ayẹwo yala ó di ọpa-idiwọn iwarere rẹ̀ mú dipo ki ó wulẹ gbojufo ìwa-àìtọ́ dá. Jesu gbiyanju lati ṣeranwọ fun awọn tí a di ẹrù ẹṣẹ rù, tí ó ní ninu awọn ọmutipara ati awọn

aṣẹwo. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nilati ṣe ohun kan naa. (Matthew 9:10-13; 21:31, 32; Luke 7:36-48; 15:1-32) Bi eniyan kan tí ó ti di Kristian bá sì dẹṣẹ, awọn Kristian miiran lè ràn án lọwọ, wọn yoo gbiyanju lati mú un padabọsipo si ojurere Ọlọrun ati si okun ti ẹmi. (Galatia 6:1; James 5:13-16) Ṣugbọn bi ẹnikan bá nhuwa ẹṣẹ laironupiwada nkọ?

15 Eiyiini jẹ otitọ nipa ọkunrin kan ní Corinth. Paul kọwe pe:

“Bi ẹnikan ti a npe ní arakunrin bá jẹ agbere, tabi olojukokoro, tabi abọriṣa, tabi ẹlẹgan, tabi ọmutipara, tabi alọnilọwọgbà; kí ẹ maṣe bá a kẹgbẹ; iru ẹni bẹẹ ki ẹ má tilẹ bá a jẹun. . ... Ẹ yọ eniyan buburu naa, kuro laarin ara, yin.1 Corinth 5:11-13.

Awọn Ẹlẹrii Jehofah ntẹle awọn itọsọna Ọlọrun ninu eyi. Bi ẹlẹṣẹ wiwuwo kan bá kọ̀ lati gba iranlọwọ tí oun kò sì pa awọn ọna iwa ibajẹ rẹ̀ tì, iru eniyan bẹẹ ni a gbọdọ lé jade tabi yọlẹgbẹ kuro ninu ijọ. Boya eyi yoo pe ori rẹ̀ wálé. Sibẹ, yala eyiini ṣẹlẹ tabi bẹẹ kọ, ipa-ọna yii ṣiṣẹ lati daabobo awọn memba ijọ tí wọn jẹ olootọ-ọkàn tí, bi ó tilẹ jẹ pe awọn funraawọn jẹ alaipe, wọn nlakaka lati di awọn ọpa-idiwọn Ọlọrun mú.—1 Corinth 5:1-8; 2 John 9-11.

16 Bi o ti wu ki o ri, iwọ lè mọ̀ nipa awọn ẹnikan tí nlọ si ṣọọṣi tí wọn sì sọ ẹṣẹ dídá di aṣa ní gbangba, tí wọn tilẹ tún ngba ibọla-funni ara-ọtọ ninu ṣọọṣi nitori ọlà tabi ìyọrí-ọlá wọn. Nipa kíkọ́ lati tẹle aṣẹ Ọlọrun lati yọ awọn ẹlẹṣẹ tí wọn kò ronupiwada lẹgbẹ, awọn ṣọọṣi nmú ki awọn miiran ronu pe awọn pẹlu lè dẹṣẹ bakan naa. (Oniwaasu 8:11; 1 Corinth 15:33) Ọlọrun kò lè tẹwọgba awọn wọnni tí nmú iru eso bẹẹ jade.—Matthew 7:15-20; Iṣipaya 18:4-8.

DIDURO LOJU-ỌNA TÍ Ó LỌ SI ÌYÈ

17 NÍ gbàrà tí o bá ti rí “oju-ọna naa tí ó lọ sibi ìyè,” o nilati maa bá kikẹkọọ Bibeli niṣo ki o baa lé duro ninu rẹ̀. Gbiyanju lati maa ka Bibeli lojoojumọ, mú ìyánhànhàn fun un dagba. (1 Peter 2:2, 3; Matthew 4:4) Yoo mú ki o gbaradi fun “iṣẹ rere gbogbo.”—2 Timothy 3:16, 17.

18 Awọn iṣẹ rere wọnni ní gbígbé ní ibamu pẹlu awọn ọpa-idiwọn iwarere Ọlọrun ninu, bakan naa níní inuure ati ṣiṣe iranlọwọ fun awọn ẹlomiran, ní pataki awọn wọnni tí wọn jẹ ibatan wa ninu igbagbọ. (James 1:27; Galatia 6:9, 10) Bi Jesu ti rí niyẹn. Yatọ si fifi apẹẹrẹ iwarere didara lelẹ, oun ṣe iwosan awọn alaisan, oun bọ awọn tí ebi npa oun sì tu awọn tí wọn ní ibinujẹ ọkàn ninu. Ní pataki ni oun nkọ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lẹkọọ tí ó sì nfun wọn lokun. Bi o tilẹ jẹ pe awa kò lè ṣafarawe awọn iṣẹ-iyanu rẹ̀, awa lè ṣeranwọ tí ó ṣeemulo fun awọn ẹlomiran, ni iwọn bi a ti lè ṣe bẹẹ, eyi tí ó sì lé sún awọn ẹlomiran lati fi ogo fun Ọlọrun.—1 Peter 2:12.

19 Ṣugbọn awọn iṣẹ rere Jesu ní pupọ sii ninu. Oun mọ̀ pe iṣẹ rere tí ó dara julọ tí a ṣe fun awọn ẹlomiran ni ríràn wọn lọwọ lati mọ ewo ni isin tí ó ṣe itẹwọgba fun Ọlọrun ati fifun wọn ní itọni nipa awọn ete Ijọba Ọlọrun. Eyi lè ràn wa lọwọ lati lé gongo-ilepa ti ìyè ayeraye ninu ayọ bá.—Luke 4:18-21.

20 Awọn Kristian lonii bakan naa nilati sapa lati jẹ́ awọn ẹlẹrii fun Jehofah. Wọn lè jẹrii nipasẹ awọn iwarere wọn, eyi tí ó ní riran awọn ẹlomiran lọwọ ninu ati pipa ara wọn mọ “lailabawọn ninu ayé.” (Isaiah 43:10-12; James 1:27; Titus 2:14) Ati pẹlu, wọn lè mú “ihinrere” naa lọ sinu ile awọn eniyan ní taarata, ki wọn sì maa tẹramọ iṣẹ yii titi Ọlọrun yoo fì sọ pe a ti ṣe é tó. (Luke 10:1-9) Iwọ kò ha fẹ́ lati ṣeranwọ fun awọn aladugbo rẹ, tí ó ní idile rẹ ninu, lati kẹkọọ nipa ijọsin tí Jehofah tẹwọgba bi? Nigba naa ìwọ, pẹlu, nilati ṣe alabapin ninu jijẹwọ igbagbọ rẹ fun gbogbo eniyan; ṣiṣe bẹẹ lè ṣeranwọ fun awọn ẹlomiran lati rí oju-ọna si ìyé. Rome 10:10-15.

[Koko Fun Ijiroro]

Eeṣe tí a fi nilati ṣayẹwo yala rere wà ninu gbogbo isin? (1, 2)

Kinni oju-iwoye Jesu nipa isin, eesitiṣe? (3-5)

Eeṣe tí ó fi ṣe pataki pe ki a ní imọ pipeye? (6, 7)

Bawo ni awọn ẹkọ ati iṣe-aṣa wiwọpọ kan ṣe forigbari pẹlu Bibeli? (8-11)

Bawo ni awọn ṣọọṣi ati Isin Kristian gidi ti rí ní ifiwera lori ọran ogun? (12, 13)

Isin Kristian tootọ ndi ipo wo mú lori ríròmọ́ awọn ọpa-idi-wọn iwarere Ọlọrun? (14-16)

Bawo ni iwọ ṣe lè duro ní oju-ọna si ìyè? (17, 18)

Afikun iṣẹ wo ni ó ṣe pataki fun awọn Kristian? (19, 20)

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 173]

“INIYELORI ATI IWA-IPÁ NÍ AUSCHWITZ”

Ninu iwe rẹ̀ tí ó ní akori yii, ẹlẹkọọ ijinlẹ nipa ayika ati idagbasoke ẹgbẹ-oun-ọgba ara Poland naa Anna Pawelcazynska ṣakiyesi pe ni Nazi Germany ”awọn Ẹlẹrii Jehofah fi irẹlẹ duro tiiri fun igbagbọ wọn eyi ti ó tako gbogbo ogun ati iwa-ipá.” Ki sì ni abajade rẹ̀? Obinrin naa ṣalaye pe:

”Ẹgbẹ awọn ẹlẹwọn kereje yii jẹ awọn eniyan tí wọn di igbagbọ wọn mú ṣinṣin tí wọn sì jagunmòlú ninu ìjà wọn lodisi ilana-eto-iṣelu Nazi. Ẹgbẹ ẹya-isin yii ti ò jẹ ti ilẹ Germany ti jẹ erekuṣu kekere kan ti ìkonilòjú alaiṣàárẹ̀ ti ó wà ní oókan-àyà orilẹ-ede tí a dáyàfò, ati ninu ẹmi aìsọ-ìgbèròpinnu-nù kan naa yii wọn nbá iṣẹ lọ ninu àgọ ìṣẹ̀ni-níṣẹ̀ẹ ní Auschwitaz. Wọn gbiyanju lati jere ọ̀wọ̀ awọn ẹlẹwọn ẹlẹgbẹ wọn . . . awọn alaboojuto ọgba-ẹwọn, ani awọn oniṣẹ-ọba fun Ẹṣọ́ pataki pẹlu (SS). Gbogbo eniyan lo mọ̀ pe kò si Ẹlẹrii Jehofah tí yoo ṣegbọran si aṣẹ kan ti oó lodisi igbagbọ isin rẹ̀.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 175]

Iwọ ha wà ní oju-ọna gboooro naa . . .

. . . Tabí ojú-ọna tóóró naa bi?