Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣiṣe Messiah na Logo

Ṣiṣe Messiah na Logo

Ori 12

Ṣiṣe Messiah na Logo

1, Kini Jehofah misi woli Isaiah (53:7-12) lati sọ nipa ohun ti o nilati ṣaju iṣelogo Messiah na?

ṢAJU iṣelogo na ijiya nilati de. Eyiyi nilati jẹ iriri Messiah “iranṣẹ” Ọlọrun na. Ni sisọ asọtẹlẹ pe eyiyi nilati jẹ ete atọrunwa nipa Messiah na, Ọlọrun misi woli rẹ̀ Isaiah ti ọgọrun ọdun kẹjọ ṣaju Sanmani Tiwa lati wipe:

“A jẹ ẹ ni ìyà, a si pọ́n ọ loju, ṣugbọn on ko yà ẹnu yẹ̀: a mu u wá bi ọdọ-agutan fun pipa, ati bi agutan ti o yadi niwaju olurẹrun rẹ̀, bẹni ko yà ẹnu rẹ̀ . . . Nitorina emi o fun u ni ipin pẹlu awọn ẹni-nla, yio si ba awọn alagbara pin ikogun, nitori o ti tú ẹmi rẹ̀ jade si iku, a si kà a mọ awọn alarekọja; o si ru ẹṣẹ ọpọlọpọ, o si nṣìpẹ̀ fun awọn alarekọja.”—Isaiah 53:7-12, JPS; Iṣe 8:32-35.

2. Lẹhin gbigbọ nipa ifisẹwọn Johannu, iru iṣẹ wo ni Jesu njẹ?

2 Ani o jẹ ọranyan fun onṣẹ ti a ran ṣáju Messiah na lati jiya fun iṣotitọ rẹ̀ si ofin Ọlọrun. Lẹhinti on ti dari ọpọlọpọ ọmọ-ẹhin ti a ti baptisi si Jesu, Herodu Antipa, ọmọ Herodu Nla, alakoso agbegbe Galili, gbe e sẹwọn, ati lẹhinna, nigba ajọyọ ọjọ ibi Herodu, a ge e li ori. (Matteu 14:1-12) Lẹhin ti Jesu gbọ nipa fifi ofin mu Johannu ati gbigbe e sẹwọn, o bẹrẹ gbe iṣẹ Johannu. “Lati igbana ni Jesu bẹrẹ si iwasu wipe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ̀.’”—Matteu 4:12-17.

3. Fun yiyàn lati di kini li o mu ki Mose jiya, bawo ni iriri Jesu si ṣe nilati ba eyini mu?

3 Gẹgẹ bi Johannu Oniribọmí, Jesu ko wasu ijọba ori ilẹ aiye ti awọn Maccabee, eyiti ọpọ awọn Ju nfẹ ki a mu padabọsipo. On nwasu “ijọba ọrun,” ijọba Ọlọrun eyiti o ní iṣe pẹlu Ọba Dafidi igbánì. Ninu ijiya rẹ̀ on ko ṣe alaidabi woli Mose. Nipa ti igbagbọ alagbara ti Mose, a kọ ọ ninu Heberu 11:25, 26 pe: ”O kuku yan ati ma ba awọn enia Ọlọrun jiya, ju ati jẹ fájì ẹṣẹ fun igba diẹ; o kà ẹgan Kristi si ọrọ̀ ti o pọju awọn iṣura Egipti lọ: nitoriti o nwo èrè na.” Niwọnbi Messiah ti nilati jẹ woli bi Mose, ti Mose si jiya ṣaju ati lẹhin yiyan a (fifi ami ororo yan a) gẹgẹ bi woli Jehofah, o jẹ ohun ti o ba itolẹsẹsẹ ti o yẹ mu pe Jesu Messiah na nilati jiya pẹlu. Niti tôtọ, awọn ijiya rẹ̀ nilati pọju ti Mose lọ.—Deuteronomi 18:15.

4. Li orukọ tani ni Mose tọ awọn enia rẹ̀ wá, bawo li eyi si ti ṣe rẹgi pẹlu ọran Jesu Kristi?

4 Ti orukọ Ọlọrun Olodumare, Jehofah, li a ran Mose pada lọ si Egipti lati ṣamọna awọn enia rẹ jade kuro li oko ẹru nibẹ. (Eksodu 3:13-15; 5:22, 23) Gan gẹgẹ bi Mose ti ba atako pade, bẹ gẹgẹ ni alafijọ rẹ̀ ni ọgọrun ọdun ekini ṣe ba a pade. F’un awọn wọnni ti ko gba a gbọ gẹgẹ bi Messiah ti Ọlọrun ran wa ni Jesu wipe:

“Emi wá li orukọ Baba mi, ẹnyin ko si gbà mi: bi ẹlomìran ba wá li orukọ ara rẹ̀, on li ẹnyin o gba. Ẹnyin o ti ṣe le gbagbọ, ẹnyin ti ngba ogo lọdọ ara nyin, ti ko wá ogo ti o ti ọdọ Ọlọrun nikan wà? Ji masee rò pe, emi o fi nyin sùn lọdọ Baba: ẹniti nfi nyin sùn wà, ani Mose, ẹniti ẹnyin gbẹkẹle. Nitoripe ẹnyin iba gba Mose gbọ, ẹnyin iba gba mi gbọ: nitori o kọ iwe nipa ti emi. Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba gba iwe rẹ̀ gbọ, ẹnyin o ti ṣe gba ọrọ mi gbọ?”—Johannu 5:43-47.

5. Eṣe ti awọn Ju fi nilati gbagbọ pe Jesu wá li orukọ Baba rẹ̀ ọrun, nigbawo ni awujọ enia si fi iru igbagbọ bẹ han?

5 Awa kiyesi bi Jesu ti ṣe da awọn wọnni lohun ti ko gba a gbọ gẹgẹbi Messiah ti nwọn si wi fun u pe: “Iwọ o ti mu wa ṣe iyemeji pẹ to? Bi iwọ ni iṣe Kristi [Ma-shi’ahh] na, wi fun wa gbangba.” Jesu sọ fun wọn pe ki nwọn jẹki awọn iṣẹ Messiah on sọrọ nipa on, wipe: “Emi ti wi fun nyin, ẹnyin ko si gbagbọ: iṣẹ ti emi nṣe li orukọ Baba mi, awọn ni njẹri mi. Ṣugbọn ẹnyin ko gbagbọ, nitori ẹnyin ko si ninu awọn agutan mi, gẹgẹ bi mo ti wi fun nyin. Awọn agutan mi ngbọ́ ohùn mi, emi si mò wọn, nwọn a si ma tò mi lẹhin.” (Johannu 10:24-27) Ṣugbọn awọn Ju kan wà ti nwọn gbagbọ pe Jesu wá li orukọ Baba rẹ̀ ọrun. Nitorina, ọjọ marun ṣáju Ajọ Irekọja ti 33 C.E., nigbati Jesu, lori kẹtẹkẹtẹ kan, wọ̀ Jerusalemu ni imuṣẹ asọtẹlẹ Sekariah 9:9, agbo enia kan ninu wọn yìn i nwọn si kigbe jade pe: “Hosanna: Olubukun li Ọba Israeli ẹniti mbọwa li orukọ [Jehofah].”—Johannu 12:1, 12, 13; Matteu 21:4-9; Marku 11:7-11; Luku 19:35-38; Orin Dafidi 118:26.

6. Li orukọ tani ni Jesu nṣọ ẹṣọ lori awọn aposteli rẹ̀ olôtọ?

6 Lakotan, li oru Ajọ Irekọja, lẹhin ṣiṣe e pẹlu awọn olotọ ọmọ-ẹhin tabi awọn aposteli rẹ̀, Jesu gbadura si Jehofah o si wipe:

“Emi ti fi orukọ rẹ han fun awọn enia ti iwọ ti fifun mi lati inu aiye wá: tirẹ ni nwọn ti jẹ ri, iwọ si ti fi wọn fun mi; nwọn si ti pa ọrọ rẹ mọ . . . Emi ko si li aiye mọ, awọn wọnyi si mbẹ li aiye, emi si mbọ wa sọdọ rẹ. Baba mìmọ, pa awọn ti o ti fifun mi mọ, li orukọ rẹ, ki nwọn ki o le jẹ ọkan ani gẹgẹ bi awa. Nigbati mo wà pẹlu wọn li aiye, mo pa wọn mọ li orukọ rẹ: awọn ti iwọ fifun mi, ni mo ti pa mọ́.”—Johannu 17:6, 11, 12.

Nitorina, ni wiwá li orukọ Jehofah, Jesu jẹ woli kan gẹgẹ bi Mose.

AMỌ̀ Ọ PẸLU NIPA AWỌN IṢẸ IYANU ATI ASỌTẸLẸ

7. Eṣe ti Mose fi ṣe awọn iṣẹ ami niwaju awọn ara Egipti ati awọn ọmọ Israeli, bawo li awọn ami rẹ̀ si ti ri ni ifiwera pẹlu awọn wọnni ti o jẹ ti Messiah?

7 Fun awọn ọmọ Israeli ati awọn ara Egipti woli Mose fihan pe on wá li orukọ Ọlọrun otitọ ati aláyè kanṣoṣo na nipasẹ ọpọlọpọ awọn iṣẹ iyanu. Awọn wọnyi jẹ “awọn ami” ti Ọlọrun fifunni ni ifihan pe Jehofah li o ran Mose. (Eksodu 4:1-30; 7:1-3; 8:22, 23; 10: 1, 2; Deuteronomi 34:10, 11) Awọn ọmọ Israeli igbánì ko bere “ami ọrun” lọwọ Mose, bẹ gẹgẹ awọn ọmọ Israeli ti ọgọrun ọdun ekini Sanmani Tiwa tase oju ọna na ni bibere iru ami bẹ lọwọ Jesu. (Matteu 16:1-4) Ki iṣe irẹnisilẹ lati wipe awọn iṣẹ iyanu ti Jesu ṣe ni ẹri si jijẹ Messiah rẹ̀ ju ti awọn eyiti Mose ṣe lọ, lọpọlọpọ.

8. Pẹlu kini ni Jesu bẹrẹ awọn ”iṣẹ ami” rẹ̀ ki si ni iyọrisi ti ”iṣẹ ami” ni lori awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ati Nikodemu?

8 Jesu ko ṣe gẹgẹ bi Mose ki o si yí omi pada si ẹjẹ, ṣugbọn nitôtọ o yí omi pada si waini ti o darajulọ nigbati ko si waini mọ nibi ase igbeyawo kan ni Kana ti Galili. Eyiyi wulẹ jẹ ibẹrẹ, gẹgẹ bi ohun ti a kọ silẹ ninu Johannu 2:11 ti wi: “Akọṣe iṣẹ ami yi ni Jesu ṣe ni Kana ti Galili, o si fi ogo rẹ̀ han; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gba a gbọ.” Nipa ti Ajọ Irekọja ti 30 C.E., akọsilẹ na sọ fun wa: “Nigbati o si wà ni Jerusalemu, ni Ajọ-Irekọja, lakoko ajọ na, ọpọ enia gba orukọ rẹ̀ gbọ nigbati nwọn ri iṣẹ ami rẹ̀ ti o ṣe.” (Johannu 2:23) Fun apẹrẹ, Nikodemu Farisi, alakoso awọn Ju ti o si jẹ memba Sanhedrin ni Jerusalemu, bẹ Jesu wò li oru o si wipe: “Rabbi, awa mọ pe olukọni lati ọdọ Ọlọrun wá ni iwọ iṣe: nitoripe ko si ẹniti o le ṣe iṣẹ ami wọnyì ti iwọ nṣe, bikoṣepe Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.”—Johannu 3:1, 2; 7:50, 51; 19:39, 40.

9. Bawo ni iru awọn iṣẹ iyanu Jesu ṣe ri ni ifiwera pẹlu ti ’Mose?

9 Mose ha wo arun ẹ̀tẹ̀ san bi? Jesu ṣe iwosan ọpọlọpọ awọn adẹtẹ ni ilẹ Israeli. Mose ha ṣe ipinya omi Okun Pupa fun gbigba awọn enia rẹ̀ là bi? Jesu rin lori awọn omi Okun Galili o si mu ki awọn omi rẹ̀ dakẹjẹ nigba ìjì lile elewu kan. Ogoji ọdun li awọn ọmọ Israeli fi jẹ manna lati ọrun wa li aginju nwọn si ku lẹhinna. Jesu pese manna kan lati ọrun wa ninu irubọ enia pipe rẹ̀, pe awọn wọnni ti njẹ ninu rẹ̀ nipa igbagbọ le waláyè titi lai. (Johannu 6:48-51) Mose ko ṣe iwosan gbogbo arun ati ailera eyiti Jesu ṣe. Moose ko ji ẹnikankan dide kuro ninu oku. Jesu ji pupọ awọn enia dide kuro ninu oku ju eyiti awọn woli Elijah ati Eliṣa ṣe lọ, ọkan ninu awọn wọnyi si ni Lasaru ti Betani, ẹniti o ti kú ti a si ti sin sinu iboji fun ọjọ mẹrin. (Johannu 11:1-45; 12:1-9) Ani awọn ọta Jesu pápá nilati faramọ ọ pe o ṣe ọpọ iṣẹ ami, nitori ti nwọn wipe: “Kili awa nṣe? nitori ọkunrin yi nṣe ọpọlọpọ iṣẹ ami. Bi awa ba jọwọ rẹ̀ bẹ, gbogbo enia ni yio gba a gbọ: awọn ara Romu yio si wa gba ilẹ ati orilẹ-ede wa pẹlu.”—Johannu 11:46-48; 12:37.

10. Bawo ni Peteru ti ṣe jẹri, fun awọn Ju ni Pentikosti ni Jerusalemu ati fun awọn Keferi ni Kesarea, nipa awọn iṣẹ iyanu Jesu?

10 Laisi sisọ ọrọ na li asọdun, nigbana, aposteli Peteru le wi fun ẹgbẹgbẹrun awọn Ju li ọjọ ajọdun Shavuoth (Awọn Ọsẹ) ti 33 C.E;, pe: “Ẹnyin enia Israeli, ẹ gbọ ọrọ wọnyi: Jesu ti Nasareti, ọkunrin ti a fi han fun nyin lati ọdọ Ọlọrun wa, nipa iṣẹ agbara ati ti iyanu, ati ti ami ti Ọlọrun ti ọwọ rẹ̀ ṣe larin nyin, bi ẹnyin tikaranyin ti mọ pẹlu.” (Iṣe 2:22) Ọdun diẹ lẹhinna Peteru yi kanna, nigbati o nsọ awọn otitọ ọran na jade, ni Kesarea, fun awọn Keferi olufifẹhan kan ti nwọn nṣe ojurere si awọn Ju, Wipe:

“Enyin na mọ ọrọ na ti a kede rẹ̀ yika gbogbo Judea, ti a bẹrẹ si lati Galili wa, lẹhin baptism ti Johannu wasu rẹ̀; ani Jesu ti Nasareti, bi Ọlọrun ti da ẹmi mimọ ati agbara le e lori: ẹniti o nkiri ṣe ore, nṣe dida ara gbogbo awọn ti Eṣu si npọn loju; nitori Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀. Awa si li ẹlẹri gbogbo ohun ti o se, ni ilẹ awọn Ju, ati ni Jerusalemu.”—Iṣe 10:37-39.

11, 12. (a) Ijọra wo li o wà lárin Jesu ati Mose gẹgẹbi woli? (b) Nipa ti asọtẹlẹ Jesu gbigbôrò julọ nkọ nipa ti imuṣẹ?

11 Mose ha iṣe woli bi? Bẹni, nitôtọ! Bẹ gẹgẹ si ni Jesu Messiah na. O sọ ọpọ owe tabi apejuwe alasọtẹlẹ. O sọ asọtẹlẹ ifihan rẹ̀ lati ọwọ Judasi aposteli on funrarẹ̀ ati bi iku on funrarẹ̀ yio ṣe ṣẹlẹ ati lati ọwọ tani, ati pẹlu pe ao ji on dide kuro ninu oku li ọjọ kẹta iku rẹ̀. O sọ asọtẹlẹ iparun Jerusalemu, eyiti yio ṣẹlẹ lati ọwọ awọn ara Romu ni 70 C.E. Asọtẹlẹ rẹ̀ ti o gbérò julọ li eyiti a ṣe akọsilẹ rẹ̀ ninu iwe Matteu ti a pamọ, ori kẹrinlelogun ati ikarundinlọgbọn, Marku, ori kẹtala, ati Luku, ori ikọkanlelogun. Asọtẹlẹ yi jẹ idahun si ibere awọn aposteli rẹ̀ niti igbati iparun Jerusalemu ati tempili rẹ̀ yio ṣẹlẹ, ati ohun ti yio jẹ “ami” ipadabọ ati “wiwa-nihin” (parousia) Messiah rẹ̀ ati ti “opin aiye.”

12 Ni ẹri si iṣedédé asọtẹlẹ yi, awọn ami asọtẹlẹ na li a muṣẹ ninu iran na ni ọgọrun ọdun ekini, ati, siwaju si i, lọna iyanu, awọn ami ti o ri bakanna ati awọn koko miran li o ti ni imuṣẹ ninu iran tiwa funrawa lati 1914 C.E., lati igba ọdun eyiti a ti ni ogun, iyan, isẹlẹ, ajakalẹ arun, inunibini si awọn ọmọlẹhin, idámu aiye, ati “ipọnju nla” alailẹgbẹ ti mbẹ niwaju.—Matteu 24:21.

13. Bawo ni Jesu ṣe ri ni ifiwera pẹlu Mose niti nini awọn asọtẹlẹ ti o sọrọ nipa rẹ̀ ti nwọn si ni imuṣẹ ninu rẹ̀?

13 Woli Mose ko ni awọn asọtẹlẹ ti o sọrọ nipa rẹ̀ ti o si ni imuṣẹ ninu rẹ̀. Ṣugbọn ninu gbogbo Iwe Mimọ li ede Heberu, lati Genesisi si Malaki, ọgọrọrun awọn asọtẹlẹ li o wà ti o ni imugṣẹ ninu Jesu lati bibi rẹ̀ si iku ati ajinde rẹ̀, lati fihan nitôtọ pe on ni Messiah na, “iru-ọmọ” na ti a nilati ”pa ni gigisẹ̀ lati ọwọ Ejo Nla na, Satani Eṣu. On funrarẹ̀ pe afiyesi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si eyi lẹhinti Ọlọrun ti ji i dide kuro ninu oku. Akọsilẹ na ninu Luku 24:25-48 sọ fun wa:

O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti oye kò yé, ti o si yigbì li aiya lati gba gbogbo eyi ti awọn woli ti wi gbọ. Ko ha yẹ ki Kristi [Ma-shi’ahh] ki o jiya nkan wọnyi ki o si wọ inu ogo rẹ̀ lọ? O si bẹrẹ lati Mose ati gbogbo awọn woli wa, o si tumọ nkan fun wọn ninu iwe mimọ gbogbo nipa ti ara rẹ̀ . . . .

“O si wi fun wọn pe, Nwọnyi li ọrọ ti mo sọ fun nyin, nigbati emi ti wà pẹlu nyin pe, A ko le ṣe alaimu ohun gbogbo ṣẹ, ti a ti kọ ninu ofin Mose, ati ninu iwe awọn woli, ati ninu Psalmu, nipasẹ mi. Nigbana li o ṣi wọn ni iye, ki iwe-mimọ ki o le ye wọn, O si wi fun wọn pe, Bẹli a ti kọwe rẹ̀, pe, ki Kristi [Ma-shi’ahh] ki o jiya, ati ki o si jinde ni ijọ kẹta kuro ninu oku: Ati ki a wasu ironupiwada ati idariji ẹṣẹ li orukọ rẹ̀, li orilẹ-ede gbogbo, bẹrẹ lati Jerusalemu lọ. Ẹnyin si li ẹlẹri nkan wọnyi.”

14. Kini Mose kọwe niti awọn ẹ̀gún lori Israeli ati nipa mimu ohun arufin kan di ẹ̀gún si Ọlọrun? Pẹlu tani li ọkan?

14 Ninu Lefitiku, ori kẹrindinlọgbọn, ati Deuteronomi 28:15-68 woli Mose ṣe akọsilẹ gbogbo ọrọ buburu ati ẹ̀gún ti yio wá sori orilẹ-ede Israeli fun kikkuna wọn lati pa majẹmu Ofin mọ pẹlu Jehofah Ọlọrun. Mose si tun kọwe:

Bi ọkunrin kan ba da ẹṣẹ kan ti o yẹ si iku, ti a si pa a, ti iwọ si so o lori igi; Ki oku rẹ̀ ki o maṣe gbe ori igi ni gbogbo oru, ṣugbọn bi o ti wu ki o ri ki iwọ ki o sin i li ọjọ na; nitoripe ẹni egun Ọlọrun li ẹniti a so; ki iwọ ki o ma ba ba ilẹ rẹ jẹ, ti [Jehofah] Ọlọrun rẹ fi fun ọ ní ini.”—Deutronomi 21:22, 23.

Dajudaju Ọlọrun li o fi ofin yi funni pẹlu nini Messiah rẹ̀ li ọkàn. Eṣe? Ki a ba le gba orilẹ-ede Israeli la, kuro lọwọ ẹ̀gún ti mbọ wa sori rẹ̀ fun riru majẹmu Ofin pẹlu Ọlọrun, Messiah na nilati ku lori igi oro kan gẹgẹ bi egun dipo Israeli.

IKU ATI IṢELOGO

15. Li ọjọ Irekọja ti 33 C.E., kini a ṣe lati mu ki awọn ti ki iṣe Ju fi iku pa Ọdọ agutan Ọlọrun?

15 Ni Nisani 14, ọjọ Ajọ Irekọja, ti ọdun 33 C.E., a pa ọdọ agutan Irekọja na lati ọwọ awọn ọmọ-ẹhin Jesu a si sẹ̀ e fun jijẹ. (Matteu 26:1-30; Marku 14:1-26; Luku 22:1-39) Ṣugbọn nipa ti ẹni na ti Johannu Baptist pe ni “Ọdọ agutan Ọlọrun ẹniti o ké ẹṣẹ aiye lọ” nkọ? (Johannu 1:29, 36) Ni ọganjọ oru lẹhin onjẹ alẹ Irekọja na, aposteli Judasi Iskariotu fi i han, awujọ kan ti o dihamọra si mu u lọ sinu itimọle, nwọn si fi i le awọn aṣaju isin lọwọ ni Jerusalemu. A si mu u wa. si igbẹjọ niwaju Sanhedrin onidajọ a si dajọ iku fun u gẹgẹ bi itumọ Ofin wọn ti wi. Nitori ailagbara wọn niti fifi ijiya iku pani, igbimọ onidajọ na fi Jesu ti a dalẹbi iku na le ọwọ Gomina Keferi na, Pontiu Pilatu, gẹgẹ bi adaluru ati arufin aṣọtẹ-si-ijọba. Itẹpẹlẹmọ awọn afinisun rẹ̀ ni fifi i kọ sori igi kan lati kú.

16. Niwaju Pilatu, kini Jesu wi nipa ijọba ati otitọ?

16 Nigbati o wà labẹ igbẹjọ niwaju Pontiu Pilatu, Jesu fihan pe ijọba Messiah on jẹ ti ọrun, ki iṣe ti ilẹ aiye ni Jerusalemu ni Agbedemeji Ila Òrùn. Nigbati Pilatu bere lọwọ rẹ̀ pe: “Iwọ ha iṣe ọba awọn Ju?” Jesu dahun pe: “Ijọba mi ki iṣe ti aiye yi: ibaṣepe ìjọba mi iṣe ti aiye yi, awọn onṣẹ mi iba ja, ki a má ba fi mi le awọn Ju lọwọ: ṣugbọn nisisiyi ijọba mi ki iṣe lati ihin lọ? Pẹlu idahun yi, Pilatu bere pe: “Njẹ ìwọ ha iṣe ọba bi?” Jesu dahun pe: 17Iwọ wipe, ọba li emi iṣe. Nitori eyi li a ṣe bi mi, ati nitori idi eyi ni mo ṣe wá si aiye, ki emi ki o le jẹri si otitọ. Olukuluku ẹniti iṣe ti otitọ ngbọ ohùn mi.”—Johannu 18:33-37.

17 Pẹlu ilọtikọ, Pilatu juwọ silẹ fun ohun ti awọn olufisun Jesu mbere fun, fifi i kọ sori igi. Ibiti a ti kàn a mọ igi na ni Golgota (’’Ibi Agbari”), tabi Kalfari, lẹhin ode Jerusalemu. A gbe e kọ larin awọn arufin meji, ’’awọn olurekọja.” Awọn wọnni ti o gboṣaṣa ninu Ofin Mose nwo Jesu lori igi gẹgẹbi “ẹni ẹgún Ọlọrun.” Biotilẹjẹpe nipa bayi a “kà a mọ awọn arufin,” sibẹ Jesu ṣi fi si ọkàn ireti Paradise ilẹ aiye fun araiye labẹ ijọba Messiah rẹ̀ lọjọ iwaju. Nitorina, nigbati arufin kan, ẹniti o wa mọ nikẹhin pe Jesu ko jẹbi ti o sì di ewurẹ irubọ fun awọn ẹlẹṣẹ, o wi fun u pe: “Jesu, ranti mi nigbati iwọ ba de ijọba rẹ.” Jesu dahun: “Lotọ ni mo wi fun ọ loni, iwọ o wà pẹlu mi ni Paradise.”—Luku 23:39-43; 22:37, NW.

18. Bawo ni Jesu ṣe ṣe iboji rẹ̀ pẹlu awọn enia buburu ati pẹlu ọlọroḷ, ipo wo li on si wà ninu isa-oku?

18 Ni nkan bi agbedemeji ọsan ọjọ Irekọja na ni Jesu ku. “O fi ẹmi rẹ̀ lelẹ fun iku.” ”O tú ẹmi rẹ̀ jade si iku.” (Isaiah 53:12, JPE; NW) Lati mu ki o ṣe rẹgi pẹlu Deuteronomi 21:22, 23, ọsan na gán li a sin i, A sin i sinu iboji titun kan ti o jẹ ti ọlọrò kan, li ọna bayi “o si ṣe iboji rẹ̀ pẹlu awọn enia buburu, ati pẹlu ọlọrò ni iku rẹ̀; nitori ko hu iwa-ipa, bẹni ko si arekereke li ẹnu rẹ̀.” (Isaiah 53:9) Nipa bayi, pẹlu, ọkàn Jesu lọ sinu Isa oku, iboji gbogbogbo fun araiye. Nibẹ li o ti jẹ otitọ nipa Jesu ti o ku: “Awọn oku ko mọ ohunkohun . . . ko si iṣẹ, tabi ete, tabi ìmọ, tabi ọgbọn, ni Isa oku, nibiti iwọ nre.”—Oniwasu 9:5, 10, AS; RB.

19. Nigbawo ati bawo ni Jehofah ṣe mu asọtẹlẹ rẹ̀ onimisi ṣẹ ti o wà ninu Orin Dafidi 16:10, esitiṣe ti ibere fi dide niti ibiti Jesu wà?

19 Biotiwukiori, Ọba Dafidi ti kọwe lọna asọtẹlẹ pe: “Nitori iwọ ki yio fi ọkàn mi silẹ ni ipo-oku; bẹni ìwọ ki yio jẹ ki Ẹni Mimọ rẹ ki o ri idibajẹ. Iwọ o fi ipa ọna iye hàn mi; ni iwaju rẹ li ẹ̀kún ayọ wà: li ọwọ ọtun rẹ ni didun-inu wà lailai.” (Orin Dafidi 16:10, 11, AS; RS) Li otitọ si asọtẹlẹ yi ti On tikararẹ̀ misi, Jehofah Ọlọrun Olodumare ji Jesu Messiah dide li ọjọ kẹta, Nisani 16, ọjọ na nigbati olori alufa Kaiafa ninu tempili ru ẹbọ “akọso eso” ikore barli si Jehofah. (Lefitiku 23:9-14; 1 Korinti 15:20, 23) Otitọ li o jẹ pe iboji ti a gbe Jesu si li a ri pe o ṣofo, ṣugbọn eṣe ti awọn aposteli rẹ̀ ko fi ri i? Eeṣe ti o fi jẹ pe nigba ogoji ọjọ lẹhin ajinde rẹ̀ yio farahan wọn lojiji yio si tun fi ara pamọ lojiji, lati fihan fun wọn pe on mbẹ láyé kuro ninu oku?—Iṣe 1:1-3; Johannu 20:1-31; Matteu 28:1-18.

20. Bawo ni Peteru ṣe ṣalaye ajinde Jesu, bawo ni Paulu si ṣe ṣalaye ajinde awọn ọmọ-ẹhin Jesu ti o ri bakanna?

20 Aposteli Peteru, ẹniti Jesu ti a ji dide na farahan fun nikọkọ nigbakan, funni li alaye fun iparada wọnyi gẹgẹ bi iru eyiti awọn angeli ẹmi ti ṣe ni ọjọ awọn woli igbánì. Peteru wipe: “Kristi pẹlu jiya lẹkan nitori ẹṣẹ wa, olôtọ fun awọn alaiṣétọ, ki o le mu wa de ọdọ Ọlọrun, ẹniti a pa ninu ara, ṣugbọn ti a sọ di áyè ninu ẹmi. Ninu eyiti o lọ pẹlu, ti o si wasu fun awọn ẹmi ninu tubu.” (1 Peteru 3:18, 19, NEB; RS; 1 Korinti 15:5; Luku 24:34) Li ajinde rẹ̀ a ṣe e si i gẹgẹ bi a ti sọ ọ tẹlẹ pe yio ṣẹlẹ si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ Li ajinde wọn:

“A gbin i li ainiyin: a si ji i dide li ogo: a gbin i li ailera, a si ji i dide li agbara. A gbin i li ara iyara; a si ji i dide li ara ẹmi, Bi ara iyara ba mbẹ, ara ẹmi si mbẹ, Bẹli a si kọ ọ pe, Adamu ọkunrin iṣaju, aláyọ̀ ọkàn li a dá a; Adamu ikẹhin ẹmi isọnidaye.

“Ará, njẹ eyi ni mo wipe, ara on ẹjẹ ko le jogun ijọba Ọlọrun; bẹni idibajẹ ko le jogun aidibajẹ . . . Nitoripe ara idibajẹ yi ko le ṣaigbe aidibajẹ wò, ati ara kiku yi ko le ṣaigbe aiku wọ. Ṣugbọn nigbati ara idibajẹ yi ba ti gbe aidibajẹ wọ, ti ara kiku yi ba si ti gbe aiku wọ bẹ tan, nigbana ni ọrọ ti a kọ yio ṣẹ pe, A gbe iku mì ni iṣẹgun.”—1 Korinti 15:43-45, 50-54.

“Nitori bi a ba ti so wa pọ pẹlu rẹ̀ nipa afarawe iku rẹ̀, a o si so wa pọ pẹlu nipa afarawe ajinde rẹ̀.”—Romu 6:5.

21. Ọlọrun ji Jesu dide lati di iru enia wo, nitorina bawo li o ṣe jẹ ti Jesu fi di iniyelori ẹbọ enia rẹ̀ mu?

21 Bẹ gẹgẹ, ẹri Iwe Mimọ fihan pe a ji Jesu Kristi dide gẹgẹ bi Ọmọ Ọlọrun ti ẹmi ninu ailékú ati aidibajẹ. (Iṣe 13:32-37) Nitorina, nigba ajinde rẹ̀ kuro ninu oku, Jesu Kristi ko gba ara enia rẹ̀ ti a fi rubọ pada kuro lori pẹpẹ Ọlọrun nipa gbigbe ara enia rẹ̀ wò lẹkansi. (Heberu 10:1-10) Bi o ti ri gan li Ọjọ Etutu ọdọdun ti a npalẹ rẹ̀ mọ́ kuro, awọn ara ẹran irubọ fun ẹṣẹ, ti a ti mu ẹjẹ wọn lọ si Ibi Mimọ Julọ, bẹ gẹgẹ ni Ọlọrun tẹwọgba ẹbọ enia Jesu ti o si palẹ ara enia Jesu mọ. Bawo? Awa ko mọ. (Heberu 13:10-13; Lefitiku, ori kẹrindinlogun) Biotilẹjẹpe Ọlọrun Olodumare ko ji Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ dide ninu ara enia, Ọmọ Ọlọrun ti a ji dide na ṣi di iniyelori tabi itoye ẹbọ enia rẹ̀ mu, eyiti o dabi ẹjẹ irubọ eyiti olori alufa Ju nmu lọ si Ibi Mimọ Julọ ninu tempili ki o ba le ṣe iwẹnumọ ẹṣẹ.

22, 23. (a) Gẹgẹ bi ẹda ẹmi nipa ajinde, kini ohun ti o ṣéṣe fun Jesu nisisiyi lati ṣe gẹgẹ bi a ti fi olori alufa ṣapẹrẹ rẹ̀ li Ọjọ Etutu? (b) Bawo ni Jesu ṣe wà ninu ipo ti o lagbara ju nisisiyi fun fifọ “ori” Ejo na?

22 Gẹgẹbi Ọmọ Ọlọrun ti ẹmi, o ṣeṣe fun Jesu Kristi lati goke pada lọ si ọrun lẹhin ogoji ọjọ lati igba ajinde rẹ̀ kuro ninu oku. Iye awọn olôtọ ọmọ-ẹhin rẹ̀ kan jẹ ẹlẹri fun igoke-re-ọrun na. (Iṣe 1:1-11) Gan gẹgẹ bi olori alufa Ju ninu Ibi Mimọ Julọ ti nwọn ẹjẹ Iwẹnumọ sara Apoti Majẹmu oniwura na, bẹ gẹgẹ ni Jesu wọ ọrun lọ niwaju Ọlọrun ti o si fi lelẹ iniyelori tabi itoye ẹbo enia rẹ̀ pipe. (Heberu 9:11-14, 24-26) Nigbana ni Ọlọrun Ọga Ogo Julọ gbe e joko li ọwọ ọtun On tikararẹ̀ gẹgẹbi “alufa titi lai nipa ẹsẹ ti Melkisedeki.’—Orin Dafidi 110:1-4; Iṣe 2:31-36; Heberu 5:10; 10:11-13.

23 Li ọna bayi a san èré fun Ọmọ Ọlọrun pẹlu ipo kan li ọrun ti o gaju eyiti on ti dimu tẹlẹ ki o to di enia pipe kan ati ki Ejo Nla na to “pa a ni gigisẹ.” O tun bẹrẹ gbe orukọ rẹ̀, Mikaeli, ti o njẹ tẹlẹ ki o to di enia, nitorina lẹkansi a tun ri “Mikaeli, olori awọn angeli” li ọrun. (Juda 9; Ifihan 12:7) “Iru-ọmọ” “obirin” Ọlọrun ti a ṣelogo na wà ni ipo ti o lagbara ju nisisiyi lati fọ ori Ejo na nigbati akoko Ọlọrun ba to.—Genesisi 3:15.

24, 25. (a) Awọn Ju ati awọn Keferi pẹlu le layọ pe Ọmọ Ọlọrun ki iṣe iru Messiah wo? (b) Ninu Filippi 2:5-11, iru ero wo ni a rọ̀ wa lati ní?

24 Bawo li o ti yẹ ki gbogbo araiye kún fun ọpẹ to, awọn Ju nipa ti ara ati awọn Keferi li apapọ, pe Messiah Ọlọrun ti a ṣeleri yio jẹ Messiah kan ti ọrun ti ko le ku, ti ki si ṣe enia kan lasan lori ilẹ aiye ti a “fi ororo yan”? gẹgẹ bi Dafidi Ọba! Labẹ imisi alasọtẹlẹ, Dafidi fi pẹlu irẹlẹ jẹwọ ẹniti a gbega yi gẹgẹ bi Oluwa rẹ̀, eyi si nilati jẹ iwa wa pẹlu. A rọ̀ wa lati ni ero onirẹlẹ yi ninu awọn ọrọ imisi ti o tẹle e yi:

25 ”Ẹ ni ero yi ninu nyin, eyi ti o ti wà pẹlu ninu Kristi [Ma.shiʹahh] Jesu. Ẹniti o tilẹ jẹ aworan Ọlọrun, ti ko ka a si iwọra lati ba Ọlọrun dọgba [sibẹ on ko ronu lati ja didọgba pẹlu Ọlọrun gba, NEB]. Ṣugbọn o bọ́ ogo rẹ̀ silẹ, o si mu àwọ iranṣe, a si ṣe e ni aworan enia. Nigbati a si ti ri i ni ìrí enia, o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, o si tẹriba titi di oju iku, ani iku lori igi oro. Nitorina Ọlọrun pẹlu si ti gbe e ga gidigidi, o si ti fi orukọ kan fun u ti o bori gbogbo orukọ. Pe, li orukọ Jesu ni ki gbogbo ekún ki o má kunlẹ, awọn ẹniti mbẹ li ọrun, ati awọn ẹniti mbẹ ni ilẹ, ati awọn ẹniti mbẹ nisalẹ ilẹ. Ati pe ki gbogbo ahọn ki o má jẹwọ pe, Jesu Kristi (Ma-shi’ahh) ni Oluwa, fun ogo Ọlọrun Baba. ”—Filippi 2:5-11. Tun wo 2 Korinti 5:16.

[Ibeere]

17. Bawo ti a ṣe kà Jesu ’mọ awọn arufin’ nigbana, ireti wo li o si fifun ọkan ninu awọn arufin na?