Ẹni Aileku na Ti O Ní “Ete Aiyeraiye” Na
Ori 2
Ẹni Aileku na Ti O Ní “Ete Aiyeraiye” Na
1, 2. Tani ẹni kanṣoṣo na ti o le ní “ete aiyeraiye” kan, kini Mose si wi nipa iru ẹni bẹ?
“ETE Aiyeraiye”! Tani le ní iru ete bẹ bikoṣe Ọlọrun ti mbẹ láyé nigba gbogbo? Efolusion, gẹgẹ bi awọn ọlọgbọn ijinlẹ ode-oni ti fi nkọni, ko le ni iru ete bẹ, niwọnbi éeṣì tabi akọsẹba, eyiti o bẹrẹ pẹlu ẹkọ ọgbọn-ori efolusion, ko bẹrẹ pẹlu ete ti o si wà laisi ete. Ni ọgọrun ọdun mẹdogun ṣaju Sanmani Tiwa yi, akéwì afunni-lofin kan ti a mọ̀ kakiri agbaiye, eyini ni, Mose ọmọ Amramu, pe afiyesi si Ọlọrun ailopin bẹ, nigbati o wipe:
2 “Ki a to bí awọn oke nla, ati ki iwọ ki o to dá ilẹ on aiye, ani lati aiye-raiye, iwọ li Ọlọrun. . . Nitoripe nigbati ẹgbẹrun ọdun ba kọja li oju rẹ, bi àná li o ri, ati bi igba íṣọ́ kan [wakati mẹrin] li oru.” —Iwe Orin Dafidi ninu Bibeli nọmba 90 ẹsẹ 2-4.
3. Eṣe ti “Ọba aiyeraiye” na ṣe le mu iru ete bẹ ṣẹ ni kikun?
3 Ni ọgọrun ọdun kini Sanmani Tiwa yi ẹnikan ti o gba Mose olufunni-li-ofin na gbọ gidigidi pe afiyesi si Ọlọrun kanna, ẹniti akoko rẹ̀ ko li opin ni igba atijọ ati li ọjọ iwaju, nigbati o kọwe pe: “Njẹ fun Ọba aiyeraiye, aidibajẹ, airi, Ọlọrun kanṣoṣo, ni ọlá ati ogo wà fun lai ati lailai. Amin.” (1 Timoteu 1:17) Iru Ọlọrun Aiyeraiye bẹ le duro tì ete rẹ̀ titi yio fi ni imuṣe si rere, laibikita fun bi o ti pẹ to, ani fun akoko ti o pẹ́ pupọ-pupọ.
4. Ẹni na ti o kọwe nipa “ete aiyeraiye” Ọlọrun so o pọ mọ nkan wo ti a ti ṣeleri tipẹtipẹ?
4 Akọwe ọgọrun ọdun kini Sanmani Tiwa yi kanna li a misi lati kọwe nipa “ete aiyeraiye” Ọlọrun ati lati so o pọ mọ Messiah na ti a ti nfojusọna fun tipẹtipẹ, “Ẹni-ororo” na, tabi “Ẹni Mimọ,” ẹniti woli Mose tikararẹ̀ sọtẹlẹ nipa rẹ̀. Nigbana lọhun awọn Pg8wọnni ti nsọ ede Siria ni Agbedemeji Ila-orun npe e ni “M shi hha”; ṣugbọn awọn Ju ti nsọ ede Griki ti ngbe ni Aleksandria, Egipti, nigbati nwọn nṣe itumọ wọn ninu Iwe Mimọ lede Hieberu ti a misi, eyiti o wá di ohun ti a npe ni Griki Septuagint, lo ede Griki na Kristos, eyiti o tumọsi ni pataki, “Ẹni-ororo.” —Wo Danieli 9:25, LXX..
5, 6. Bawo ni awọn olutumọ ode oni ṣe dá iṣoro silẹ nipa ohun ti Ọlọrun ṣeto rẹ̀ niti Messiah na?
5 Biotiwukiori, awọn olutumọ ode-oni fun awọn iwe ti akọwe ọgọrun ọdun kini ti da iṣoro kan silẹ fun wa. Lati ọgọrun ọdun kẹrindinlogun siwaju awọn olutumọ Bibeli li ede Gẹsi ti sọrọ nipa rẹ̀ gẹgẹ bi “ete aiyeraiye” Ọlọrun. * Ṣugbọn laipẹ yi diẹ ninu awọn olutumọ Bibeli kan tumọ gbolohun ọrọ ede Griki na gẹgẹ bi “iwewe igba pipẹ.” Nipa bayi a sọ pe Ọlọrun ni “iwewe” kan ti o ni iṣe pẹlu Messiah.
6 Fun apẹrẹ, itumọ lẹta na ni 1897 (C.E.) si awọn ara Efesu, ori kẹta, ẹsẹ kẹsan titi de ikọkànla, lati ọwọ J. B. Rotherham, kà pe: “Ati lati mu wa si imọlẹ ohun ti iṣakoso ohun ijinlẹ mimọ na jẹ eyiti a ti fi pamọ fun igba pipẹ ninu Ọlọrun, ẹniti o da ohun gbogbo: ki a ba le sọ ọ di mimọ nisisiyi fun awọn alagbara ati awọn ijoye awọn ohun ti mbẹ li ọrun, nipasẹ ijọ, ọgbọn titobi Ọlọrun,—gẹgẹ bi iwewe igba pipẹ eyiti on ṣe ninu ẹni-ororo na.” Ani pada sẹhin de 1865 C.E. The Emphatic Diaglott, lati ọwọ olotu iwe irohin na Benjamin Wilson, ní gbolohun ọrọ na, “gẹgẹ bi iwewe fun igba pipẹ, eyiti on ṣe,” ninu. Awọn itumọ Bibeli miran laipẹ yi li a le tọkasi ti o yan lati tumọ ọrọ Griki na lọna bayi. *
7, 8. Apejuwe wo ni C. T. Russell tẹjade, kini iwe rẹ̀ si wi nipa akori rẹ̀?
Efesu 3:11 ti a gbeka itumọ ti o yatọ lori ọrọ Griki na. Eyiyi ṣalaye aworan kan ti o kun oju iwe kan pẹlu akori na “Ṣati Igba Pipẹ.” Inu wa dun lati mu ṣati yi jade nihin fun gbogbo awọn olufifẹhan lati yẹwo. Iru “Ṣati Igba Pipẹ Ti O nṣapejuwe Iwewe Ọlọrun” kanna wà ninu iwe na ti a npe ni “Iwewe Atọrunwa fun Igba Pipẹ,” lati ọwọ C. T. Russell ni 1886.
7 A ṣe itẹjade kan ni September, 1881, ninu Zion’s Watch Tower nì Pittsburgh, Pennsylvania, U.S.A., lati ọwọ olotu ati oluṣewe na Charles Tae Russell, pẹlu akori na “Iwewe Igba Pipẹ,” lori8 Laibikita fun awọn alebù ti a le ri ninu rẹ̀ loni, “Ṣati Igba Pipẹ” yi ṣiṣẹ lati fi ọna ironu atọkanwa han ti a gbeka ironu na pe Ọlọrun Olodumare, Ọlọgbọn-Gbogbo na ni “iwewe” kan. Awọn ọrọ ti o bẹrẹ Ori 1 ninu iwe yi wipe:
Akori na fun awọn Ekọ wọnyi—“The Divine Plan of the Ages” (“Iwewe Atọrunwa fun Igba Pipẹ”), damọran iṣisẹntẹle ninu eto Ọlọrun, ti Ọlọrun wa ti mọ tipẹtipẹ ti o si wà letoleto. Awa gba awọn ẹkọ ifihan Atọrunwa gbọ pe a le ri wọn pe nwọn lẹwa nwọn si wà ni iṣọkan lati ibẹrẹ yi, ko si le ti ibomiran wá.
9. (a) O kere o pọ kini koko ti iwe ti ipinkiri rẹ̀ pọ yi tẹnumọ? (b) Sibẹ kini ibere ti o gbe dide nipa iwewe kan ati Ọlọrun?
9 Iwe yi ní ipinkiri ti o ju adọta ọkẹ lọna mẹfa lọ, ninu iye awọn ede kan. Ipinkiri rẹ̀ dopin ni ọdun 1929 C.E. Fun ohun kan, o dari awọn onkawe rẹ̀ si Bibeli o si fihan pe Ọlọrun Alayè ntẹsiwaju. O ntẹsiwaju nipa ohun ti o ní lọkan fun araiye ti njiya. Awa mọ pe igba gbogbo li enia nṣe iwewe iṣẹ kan ṣugbọn lẹhin iru iwewe bẹ fun iṣẹ ni ete kan wà lati muṣẹ. Ṣugbọn koko ti a njiroro le lori ni pe, Ọlọrun Alagbara-Gbogbo, Ọlọgbọn-Gbogbo ha nilati ṣe iwewe kan fun iṣẹ, ọna kan ti o ti wà nilẹ lati tẹle li akoko igbati on ṣe ipinnu lati ṣe ohun kan li aṣeyọri, nipa bayi ki o sọ ọ di ọranyan fun ara rẹ̀ gẹgẹ bi Ọlọrun ti ko le yipada latì rọmọ ọna iwewe *
yi laisi yiyà si apakan? Tabi, on ha le bojuto awọn iṣẹlẹ ojiji ati awọn ohun ti o ṣeṣi ṣẹlẹ nitori ominira ati yiyan ti awọn ẹda rẹ̀ ni, lẹsẹkẹsẹ ati laisi iro-tẹlẹ, sibẹ ki o si ba gongo rẹ̀? On ha nfẹ iwewe kan bi? Nitotọ, lẹhinti on ti mu ete rẹ̀ ṣẹ, awa le ṣe ayẹwo akọsilẹ awọn iṣisẹ rẹ̀ ki a si fa ila tabi ya aworan ọna ti on ti gba. Ṣugbọn a ha wewe rẹ̀ lọna bẹ bi?ỌLỌRUN ETE KAN
10. Kini ọrọ Griki na pro’the-sis tumọ si ni gidi, bawo li awọn Ju si ti ṣe lò o ninu Greek Septuagint?
10 Ẹniti o kọ awọn ọrọ inu Efesu 3:11 li ede Griki ni ibẹrẹ ha fẹ lati fihan pe Ọlọrun Ẹlẹda na ní iwewe kan nipa Messiah Rẹ̀? Kini on rò nigbati, ninu lẹta rẹ̀ ti o kọ li ede Griki ọgọrun ọdun kini, on lo ọrọ na pro’the-sis? Ni gidi o tumọsi “lila silẹ tabi ṣaju,” nipa fifi nkan kan si iwaju. Idi ni yi ti awọn Ju ti o wà ni Aleksandria, nigbati nwọn ntumọ si ede Griki awọn Iwe Mimọ lede Heberu ti a misi, fi lo ọrọ Griki yi nipa akara mimọ ti a gbeka ori tabili oniwura ninu yara Ibi Mimọ ninu agọ mimọ fun ijọsin ti woli Mose gbekalẹ. Ni kukuru a npe akara yi ni akara ifihan, ṣugbọn Greek Septuagint Version sọrọ nipa rẹ̀ gẹgẹ bi “akara tabi cake ifihan” (prothesis). Nitorina awọn akara wọnyi, nipa gbigbe wọn kalẹ lori tabili oniwura, li a fihan, titun rẹ̀ li a si nmu wa li ọjọ isimi ọsọsẹ.—2 Kronika 4:19.
11. Nigbana, kini “pro’the-sis” Ọlọrun?
11 Ọrọ na pro’the-sis li a tun lo lati tumọsi “gbolohun ọrọ” kan, “asan-tẹlẹ” kan, ati, ninu ofin ede ọrọ, yio tumọsi “ibatan larin ọrọ” (preposition). A si tun loo pẹlu lati tumọsi “ọrọ iṣaju,” “ifiṣaju lakọkọ.” Nitori pe a lò ọrọ na lati tumọsi opin kan tabi gongo kan ti a pete, tabi fifi ohun kan si iwaju ẹni fun aṣeyọri tabi ri gba, a lo o lati tumọsi “ete.” (Lori eyi, wo A Greek English Lexicon lati ọwọ Liddell and Scott, Volume II, oju iwe 1480-1481, atuntẹ ti 1948, labẹ pro’the-sis.) Itumọ ikẹhin yi ni eyiti o pọ julọ ninu awọn olutumọ Bibeli ode-oni tẹwọgba. Nitorina “pro’the-sis” Ọlọrun ni ipinnu rẹ̀, olori ipinnu rẹ̀, ete rẹ̀. *
12. Bawo ni awọn olutumọ ode oni ṣe tumọ ọrọ Griki na pro’the-sis eyiti ton ai-o’non (“ti igba pipẹ”) tẹlẹ?
12 Ninu Efesu 3:11 gbolohun ọrọ na ton ai-o’non li o tẹlẹ e, ti o tumọsi ni gidi “ti igba pipẹ” * Nitorina akopọ ọrọ yi li awọn kan tumọ si “ete Sanmani” * tabi “ete igba pipẹ kan” * tabi “ete igba lailai” * tabi ipinnu ataiyebaiye” ati awọn miran gẹgẹ bi “ete aiyeraiye.” *
13 “Ete igba pipẹ” Ọlọrun ni “ete aiyeraiye” Rẹ̀. Bawo li eyini ṣe ri bẹ? O dara, nihin, igba pipẹ kan (Gẹsi, “an age”) yio tumọsi igba akoko kan ti ko daju ṣugbọn ti o gun pupọ ninu awọn ọran enia, pẹlu itẹnumọ pupọ lori gigun akoko ninu igba na ju lori iṣe-pataki rẹ̀ tabi awọn ohun ti o rọ̀ mọ ọ.
13, 14. Eṣe ti a fi le wipe “ete igba pipẹ” Ọlọrun jẹ “ete aiyeraiye” rẹ̀?
14 Nipa bayi “ete igba pipẹ” tabi “ete sanmani” Ọlọrun ko ni tumọsi “ete” kan ti o ní iṣe pẹlu awọn akoko kan ti a yan sọtọ gẹgẹ bi “igba awọn babanla,” “igba awọn Ju,” “igba Ihinrere,” “igba Ẹgbẹrun ọdun.” Kakabẹ, itẹnumọ na wà lori akoko, lori awọn akoko gigun kan. Fun igba lati tẹle igba, igba kọkan nilati ni ibẹre kan ati opin kan. Sibẹ awọn igba ti ntẹle ara wọn yio mu ki akoko na gun. Niwọnbi a ko si tii sọ pato iye igba, ninu gbolohun ọrọ na, “ete awọn igba pipẹ,” iye igba na nilati jẹ ailopin. Nitorina gbolohun ọrọ na “ete awọn igba pipẹ” mu ki apapọ iye akoko ti o kàn jẹ lailai, o si jẹ “ete” titilai, laisi opin kan ti a samisi nitotọ. Lọna bayi “ete” wa di ọran aiyeraiye, o si di “ete aiyeraiye.” Ete Ọlọrun niti Messiah tabi Ẹni-ororo rẹ̀, ní ibẹrẹ kan, ṣugbọn a yọda fun igba akoko pipẹ lati kọja ki a to mu ete na ṣẹ. * Fun “Ọba aiyeraiye” ọran akoko nihin ki iṣe iṣoro.
KI IṢE ẸNIKAN TI KO LI ORUKỌ
15. Nigbati a bere orukọ Rẹ̀, kini Ọlọrun wi fun Mose ni Sinai?
15 Ọba Aiyeraiye yi ki iṣe Ẹnikan ti ko li orukọ. Eksodu 3:14.
On ti fun ara rẹ̀ li orukọ kan on si ti mu ki ẹniti on jẹ di mimọ̀ fun wa. Ohun ti on npe ara rẹ̀ sọrọ nipa ete, nini ti on ni gongo kan. Bawo li a ṣe mu otitọ jade daradara to li akoko na nigbati Ọlọrun, nipasẹ angeli rẹ̀, dojukọ Mose, isansa na lati Egipti, nibi igbo ti njo lẹba Oke Sinai ni Arabia, ni ọgọrun ọdun kẹrindinlogun B.C.E.! A sọ fun Mose pe ki o pada si Egipti ki o si ṣamọna awọn enia rẹ̀ ti o wà li oko ẹrú wa si ominira. Ṣugbọn bi awọn enia Mose ba nilati bere orukọ Ọlọrun na ti o ran a si wọn gẹgẹ bi aṣaju wọn nkọ? Kini ohun ti on nilati sọ fun wọn? Mose fẹ lati mọ̀. Itan igbesi aiye on funrarẹ̀ sọ fun wa: “Ọlọrun si wi fun Mose pe, EMI NI ẸNITI O WÀ: o si wipe, Bayi ni ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, EMI NI li o ran mi si nyin.”—16. Nipa idahun rẹ̀ fun Mose, Ọlọrun ha wulẹ nsọrọ nipa wiwà rẹ̀ tabi nipa kini?
16 Nihin Ọlọrun ko sọrọ nipa wiwà rẹ̀. Ẹnikan le ro pe bẹ ni lati inu ọna ti awọn olutumọ kan gba tumọ rẹ̀ si ede Gẹsi awọn ọrọ Heberu na eh-yeh’ a-sher’ eh-yeh’ ati eh-yeh’. Fun apẹrẹ, The Jerusalem Bible (itumọ Gẹsi) ti 1966, kà pe: “Ọlọrun si sọ fun Mose, ‘Emi ni ẹniti Mo Jẹ. O nba a lọ pe, ‘Eyi li ohun ti o gbọdọ sọ fun awọn ọmọ Israeli: “Emi ni ti ran mi si nyin.” ’ ” Biotiwukiori, nitotọ Ọlọrun nsọrọ nipa jijẹ nkan kan. Eyiyi li a fihan siwaju si i lati inu itumọ Twenty-Four Books of the Holy Scriptures (Awọn Iwe Mẹrinlelogun ninu Iwe Mimọ) lati ọwọ Rabbi Isaac Leeser, bayi pe: “Ọlọrun si sọ fun Mose pe, EMI YIO JẸ OHUN TI EMI YIO JẸ: o si wi pe, Bayi ni iwọ yio wi fun awọn ọmọ Israeli, EMI YIO JE ti ran mi si nyin.” *
17. Bawo ni Rotherharma ṣe tumọ Eksodu 3:14 ati alaye lori rẹ̀?
Eksodu 3:14 bayi pe: “Ọlọrun si sọ fun Mose, Emi Yio Jẹ ohunkohun ti mo ba fẹ. O si wipe—Bayi ni ki o wi fun awọn ọmọ Israeli, Emi Yio Jẹ ti ran mi si nyin.” Alaye isalẹ lori ẹsẹ yi sọ, li apakan: “Hayah, [ọrọ na ti a lo fun ‘jẹ̀’ loke] ko tumọsi ‘lati dà’ ni pataki tabi wiwà, bikoṣe riri pẹlu ọgbọn ironu . . . Ohun ti on yio jẹ li a fi silẹ laisọ—On yio wà pẹlu wọn, oluranlọwọ, olufunni-lagbara, oludande.” Nipa bayi itọka si Ọlọrun nihin ki iṣe niti wiwà rẹ̀ funrarẹ̀, kakabẹ, ohun ti on ní lọkan lati jẹ fun awọn miran.
17 Pẹlu itẹnumọ, The Emphasised Bible, lati ọwọ Joseph B. Rotherham, tumọ18. Nigbawo ni Ọlọrun kọkọ pinnu ohun ti on nilati dà tabi jẹ?
18 Bẹ gẹgẹ si eyi ni nigbati ọdọ kan, nigbati o ndagba, rò ninu ara rẹ̀ o si sọ fun ara rẹ̀ pe: ‘Kini emi yio fi igbesi aiye mi ṣe? Kini emi yio sọ ara mi dà?’ Ko yatọ si eyi, nigbati Ọlọrun otitọ ati aláyé na nikan wà, on nilati pinnu ohun ti on yio ṣe pẹlu wiwa rẹ̀, ohun ti on yio sọ ara on dà, ohun ti on yio jẹ. Lẹhin aiyeraiye ṣaju iṣẹda ninu dida-nikan-wà rẹ̀, on fẹ lati di Ẹlẹda. O gbe ete kan kalẹ fun ara rẹ̀.
19. Bawo ni Ọlọrun ṣe sọ orukọ rẹ̀ ninu Ofin Mẹwa?
19 Ṣugbọn o, orukọ na eyiti a fi mọ Ọlọrun otitọ ati alayè na jakejado gbogbo Iwe Mimọ ti a misi ki iṣe Ehyehʹ, tabi, “Emi Yio Jẹ.” Ni ọdun 1513 B.C.E., ni Oke Sinai, nigbati Ọlọrun lọna iyanu kọ awọn Ofin Mẹwa sori awọn wàlá okuta meji ti o si fi wọn fun woli Mose, Ọlọrun funrarẹ̀ li o pe orukọ ti o yan fun ara rẹ̀ na jade. Nigbati o nkọ lati ọtun si osi, Ọlọrun kọ lẹta Heberu na Yod, lẹhinna Heh, o si tun kọ Waw, nikẹhin o kọ Heh. Laisi iyemeji Ọlọrun kọwe lọna ti a gba nkọ awọn lẹta Heberu nigba lailai gẹgẹ bi: yxy2; ki iṣe gẹgẹ bi awọn lẹta Heberu ti ode-oni: yhwhʹ. Awọn lẹta ti o ri bakanna lede Gẹsi, nigbati a ba kà a lati ọtun si osi, ni HWHY; tabi, ni Latin igbánì, HVHJ. Gbogbo lẹta mẹrin na jẹ kọnsonanti, laisi fawẹli larin awọn kọnsonanti wọnyi.
20. Bawo li a ṣe npe orukọ Ọlọrun, bi a ti ṣe gbe e ka ori lẹta mẹrin ti Heberu?
20 Bi Jehofah ti ṣe pe orukọ atọrunwa yi fun Mose gán li a ko mọ̀ nitorina loni. Fun ọpọ ọgọrun ọdun awọn akọwe lede Latin npe e ni Jehova. Ọpọ awọn ọmọwe Heberu lode oni yan lati pe orukọ na ni Yahweh, tabi Yehwah paapaa. Nipa bayi, bi ọmọ kan ko ti fun baba rẹ̀ li orukọ, bẹ gẹgẹ ni ẹda ko ni fun Ẹlẹda rẹ̀ li orukọ. Ẹlẹda na li o sọ ara rẹ̀ li orukọ.
21. (a) Ni jijẹ ọrọ iṣe nitotọ, kini orukọ na Jehofah tumọ si? (b) Eṣe ti o fi tọna lati lo orukọ na loni?
21 Orukọ mimọ yi nitotọ li a loye pe o jẹ ọrọ iṣe kan, ọrọ iṣe Heberu kan ha-vah’ ti ko ṣe pato. Nipa bayi yio tumọsi “On Mu Ki O Wà.” Nisisiyi, lẹhin gbogbo abajade, idi kan nilati wà; lẹhin gbogbo idi ti o lọgbọn ninu, tabi ohun ti o fà a, ete kan nilati wà. Gẹgẹ bi iwa ẹda, nigbana, orukọ atọrunwa na ti o tumọsi “On Mu Ki O Wà” fihan pe ete wà ninu rẹ̀. O sami si Olu-jẹ ojulowo orukọ na gẹgẹ bi Elete na. Dajudaju ninu ipo yi li on farahan Mose nibi igbẹ ti njo ni Oke Sinai, ohun ti on si ti fi si iwaju rẹ̀ lati ṣe li on fihan Mose. Ni titẹnumọ itoye pipẹtiti tabi lailai ti orukọ atọrunwa na ni, Ọlọrun sọ siwaju fun Mose pe: “Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli; [Jehofah] Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o ran mi si nyin: eyi li orukọ mi titilai, eyi si ni iranti mi lati randiran.” (Eksodu 3:15) Orukọ titilai na koiti dẹkun lati jẹ Tirẹ̀ loni. O jẹ orukọ ti a tẹwọgba fun wa lati lo loni.
OLUṢE ITAN FUN IRE ENIA
22. (a) Bawo ni Jehofah ṣe ṣe orukọ fun ara rẹ̀ niti ọran Egipti igbánì? (b) Ẹkọ ti ntunni-ninu wo li eyini fun wa loni?
22 Li awọn ọjọ woli Mose, Jehofah, Ọlọrun otitọ ati alàyè na ṣe itan li ọna ti on gba ba Egipti igbanì lò, olupọn awọn atọmọdọmọ Abrahamu, Isaaki ati Jakobu loju. O ṣe orukọ ti o logo fun ara rẹ̀ nipa gbigba awọn enia rẹ̀ ti a kó lẹru silẹ lati ọwọ agbara aiye ti Pg16 o ti mura ogun silẹ daradara. (Jeremiah 32:20; 2 Samueli 7:23; Isaiah 63:14) Eyi mu u da wa loju pe aiye ọgọrun ọdun lọna ogun C.E. ti o ti mura ogun silẹ kikan-kikan yi ki iṣe ohun bàbàrà kan fun u lati dojukọ gẹgẹ bi ọta ki on ba le dá araiye silẹ. Bi on ti yọda fun Farao ti Egipti igbánì lati di alagbara ki o si mu ipọnni-loju rẹ̀ ti npaniku tẹsiwaju lori awọn enia Mose, bẹ gẹgẹ ni Jehofah ti yọda fun awọn olupọnni-loju enia buburú lati di alagbara lori gbogbo aiye pẹlu ipọnju nlanla ti o yọrisi fun gbogbo enia. Idi kan wà fun ṣiṣe bẹ. O jẹ lati fi wọn pamọ, lati pa wọn ninu itimọle, fun ọjọ ti o yan lati pa wọn run. Nitorina, fun itunu awọn enia ti a ti di ẹ̀rù wiwuwo le lori, o misi ọlọgbọn Ọba Solomoni lati wipe:
“Fi iṣẹ rẹ le [Jehofah] lọwọ, a o si fi idi iro-inu rẹ kalẹ. [Jehofah] ti ṣe ohun gbogbo fun [ete] [Heberu: ma‘a-nehʹ] rẹ̀: nitotọ, ani awọn enia buburu fun ọjọ ibi.”—Owe 16:3, 4.
23. Ibalo Ọlọrun pẹlu awọn agbara aiye igbánì funni ni idaniloju kini lati reti fun akoko tiwa nipa awọn oṣelu alagbara?
23 Lati ọdun na 1914 C.E. o ti jẹ “ọjọ ibi” fun awọn eto ijọba ti o ti la awọn ogun agbaiye meji já ati awọn ijọngbọn agbaiye ti o ba a rìn. Fun ọpọ ọdun nisisiyi, awọn oṣelu alagbara giga-giga li o ti jẹgaba lori aiye, ti nwọn nfi pẹlu ifura wò oju ara wọn ninu ijakadi wọn fun jijẹ olori aiye. Jehofah Oluwa Ọba Alaṣẹ, ẹniti o ti dá ohun gbogbo fun ete rẹ̀, nilati ní ete ti o lọgbọn ninu nipa awọn ti o njijakadi wọnyi fun ijẹgaba lori aiye. O wà ninu akọsilẹ pe on gbe ete kan kalẹ nipa awọn agbara aiye “buburu!” ni awọn akoko Bibeli ni igba lailai. Gẹgẹ bi idaniloju ohun ti awa le reti fun akoko wa, gbogbo ohun ti on pete nipa awọn agbara aiye ti o ti wà ṣaju wọnni li on tì muṣẹ.
24. (a) Biotilẹjẹpe on jẹki Assiria de ipo ijẹgaba ninu aiye, kini Jehofah nṣe nipa rẹ̀? (b) Eṣe ti a ko le sọ wipe asọtẹlẹ Jehofah ninu Isaiah 14:24-27 kuna?
24 Fun apẹrẹ, Ilẹ Ọba Asiria rọpo Egipti igbanì Nahumu, ori 1-3) Nipa bayi ko si ikuna kankan fun ete Jehofah gẹgẹ bi a ti sọ ọ li eyiti o ju ọgọrun ọdun ṣaju nipasẹ Isaiah woli rẹ̀ ninu awọn ọrọ wọnyi:
ninu ijẹpataki iṣelu ati iṣẹ ogun o si di agbara aiye keji ninu itan Bibeli. Ṣugbọn ani ninu ibẹrẹ agbara rẹ̀ papa lori araiye, ko si igba kan ti o le ṣe fonte ṣiṣẹgun tabi pipa Jerusalemu run, olu ilu Ijọba Juda. Kaka bẹ̀, Jerusalemu fojuri iparun Ninefe, olu ilu Asiria. Eṣe ti eyi fi ri bẹ? Nitoripe Agbara Aiye Asiria buru. Jehofah, Ọlọrun Olodumare, ti yọda fun u lati de ipo ijẹgaba lori aiye ati lati ṣiṣẹ buburu, ni pataki si awọn enia anyanfẹ rẹ̀. Ṣugbọn on ti pete lati fi agbara aiye buburu na pamọ fun “ọjọ ibi” li akoko Rẹ̀ ti o yàn. Nitorina ni nkan bi 632 ṣaju Sanmani Tiwa Ninefe olu ilu Asiria ṣubu sọwọ apapọ awọn ara Media ati Kaldea a si pa a run. (“[Jehofah] awọn ọmọ-ogun ti bura, wipe, Lotọ gẹgẹ bi mo ti gberò, bẹni yio ri, ati gẹgẹ bi mo ti [pete], bẹni yio si duro: Pe, emi o fọ awọn ara Assiria ni ilẹ mi, ati lori oke mi li emi o tẹ̀ ẹ mọlẹ labẹ ẹsẹ: nigbana li ajaga rẹ̀ yio kuro lara wọn, ati ẹrù rẹ̀ kuro li ejika wọn. Eyi ni [ete] ti a [pete] lori gbogbo aiye: eyi si ni ọwọ ti a nà jade lori gbogbo orilẹ-ede. Nitori (Jehofah) awọn ọmọ-ogun ti [pete], tani yio si sọ ọ di asan? ọwọ rẹ̀ si nà jade, tani yio si dá a pada?”—Isaiah 14:24-27.
25. Ninu asọtẹlẹ na, kini “igbimọ” tumọ si, esitiṣe?
25 Ọlọrun Olodumare na, Ọlọgbọn-Gbogbo ko gbimọ pọ pẹlu ẹnikẹni li ọrun lati le tọ Ọ sọna ninu ilana iṣẹ rẹ̀. “Tali o ti tọ́ ẹmi [Jehofah] tabi ti iṣe igbimọ rẹ̀ ti o kọ́ ọ?” ni ibere ti o ba a mu gẹ ti a gbe dide ninu asọtẹlẹ Isaiah 40:13. (Pẹlu, Jobu 21:22; 36:22; Romu 11:34) “Igbimọ” Rẹ̀ jẹ tirẹ̀ funrarẹ̀, laigbarale ẹgbẹ oludamọran fun iranlọwọ ninu idajọ ati ipinnu ti o tọ́. Nipa bayi, “igbimọ” rẹ̀ nihin gborò ju ero imọran lọ; o duro fun ipinnu ti a fihan, aṣẹ rẹ̀. Nipa ilo ọrọ na “igbimọ” ninu Iwe Mimọ, M’Clintock and Strong’s Cycelopaedia, Iwe II, oju iwe 539, wipe: “Ni afikun si sisọ bi itumọ ọrọ na ti jẹ gan, gẹgẹ bi gbigberò pọ pẹlu awọn enia, a tun lò o ninu Iwe Mimọ fun awọn aṣẹ Ọlọrun, awọn aṣẹ rẹ̀ gẹgẹ bi Ọlọrun.”
26.Ni jijẹki Babiloni rọpo Assiria ninu ipo ijẹgaba lori aiye, kini Jehofah npete lati ṣe?
26 “Igbimọ” Ọlọrun Olodumare, Ọlọgbon-Gbogbo, ti o funrarẹ̀ ṣe, li awọn enia tabi awọn ẹmi eṣu ko le bì ṣubu. Eyiyi jẹ otitọ nipa igbimọ Rẹ lodi si Agbara Aiye Assiria. O tun fihan pe o jẹ otitọ pẹlu nipa agbara aiye titun ti o tẹle e, Agbara Aiye titun ti Babiloni, agbara aiye kẹta ninu itan Bibeli. Eyiyi ni agbara aiye na ti o pa Jerusalemu run, fun igba ekini, ni ọdun 607 B.C.E. Ni ṣiṣe bẹ, agbara aiye yi fihan pe on “buru.” Nitorina Jehofah pa a mọ pẹlu de “ọjọ ibi” ni akoko rẹ̀ funrarẹ̀ ti o paṣẹ. Ki On to yoda fun Babiloni lati pa Jerusalemu run ki o si tipa bayi gbe iwa buburu ara-ọtọ dide ṣaju Rẹ̀, Ọlọrun misi woli rẹ̀ Jeremiah lati wipe: “Nitorina gbọ imọ [Jehofah], ti o ti gbà si Babeli: ati ero rẹ̀, ti o ti gba si ilẹ awọn ara Kaldea.”—Jeremiah 50:1, 45.
27. Ninu ikẹkọ Bibeli, kini Jeremiah ati Danieli ri ti a kọwe rẹ̀ silẹ ninu asọtẹlẹ Isaiah nipa iṣubu Babiloni?
27 Woli Jeremiah yi mba a lọ lati waláyé labẹ ábò Ọlọrun la iparun Jerusalemu ati tempili rẹ̀ já lati ọwọ awọn ọmọ-ogun Babiloni ni ọdun 607 B.C.E. Ṣugbọn ko waláye to lati ri imuṣẹ awọn asọtẹlẹ rẹ lori Babiloni “buburu” na. Biotiwukiori, itan aiye ati itan Bibeli ṣe akọsilẹ ibiṣubu Agbara Aiye Babiloni, eyiti o ṣẹlẹ ni ọdun 539 B.C.E., ni awọn ọjọ Danieli, ori 5) Eyiyi pẹlu si tun fi idi awọn asọtẹlẹ woli Isaiah, ti o ti wà ṣaju tipẹtipẹ, mulẹ, ẹniti ki iṣe pe o tọkasi ibiṣubu Agbara Aiye Babiloni nikan ni, ṣugbọn o sọ asọtẹlẹ orukọ aṣẹgun ara Persia ẹniti Ọlọrun yio lo lati ṣe ibiṣubu Babiloni. Ninu ikẹkọ Bibeli wọn funrawọn, nigbati awọn woli Jeremiah ati Danieli gbe akọsilẹ asọtẹlẹ Isaiah ni ọgọrun ọdun kẹjọ B.C.E., nwọn ri awọn ọrọ wọnyi ti o jẹ ti Jehofah, Ọlọrun wọn ti a kọ:
”Ti o wi niti Kirusi pe, Oluṣọ-agutan mi ni, yio si mu gbogbo ifẹ mi ṣẹ: ti o wi niti Jerusalemu pe, A o kọ ọ: ati niti tempili pe, A o fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ. Bayi ni [Jehofah] wi fun ẹni-ororo rẹ̀, fun Kirusi, ẹniti mo di ọwọ ọtun rẹ̀ mu, lati ṣẹgun awọn orilẹ-ede niwaju rẹ̀; emi o si tú amure ẹgbẹ awọn ọba, lati ṣi ilẹkun abawọle rẹ, ki ilẹkun ode rẹ̀ maṣe jẹ titi. Emi o lọ siwaju rẹ , . . . ki iwọ le mọ pe, emi [Jehofah], ti o pe ọ li orukọ rẹ, li Ọlọrun Israeli. Nitori Jakobu iranṣẹ mi, ati Israeli ayanfẹ mi, emi ti pe ọ li orukọ rẹ: mo ti fi apele kan fun ọ, bi iwọ ko tilẹ ti mọ̀ mi. Emi ni [Jehofah], ko si ẹlomiran, ko si Ọlọrun kan lẹhin mi: mo dì ọ li amure, bi iwọ ko tilẹ ti mọ mi. Ki nwọn le mọ̀ lati ila-orùn, ati lati iwọ-orùn wá pe, ko si ẹnikan lẹhin mi: emi ni [Jehofah], ko si ẹlomiran.”
28. Ninu ori ti o tẹle e ninu Isaiah, kini Jehofah wi nipa Kirusi ara Persia?
28 Awọn ọrọ iyanu wọnni li a le ri loni ninu Iwe Akajọ ti Isaiah ti a ri ninu Okun Oku ni ọdun 1947 ti a si ti kọ ni ọgọrun ọdun keji B.C.E. Awọn ọrọ na li a ri ninu ohun ti gbogbo enia mọ̀ gẹgẹ bi Isaiah lati ori kẹrinlelogoji, ẹsẹ kejidinlọgbọn, titi de ori karundinladọta, ẹsẹ kẹfa. Ninu ẹsẹ ti o tẹle e lẹhinna, Ọlọrun sọrọ nipa Kirusi gẹgẹ bi “ọkunrin na ti o mu imọ mi ṣẹ,” ninu awọn ẹsẹ ti a fayọ nisisiyi:
“Ẹ ranti eyi, ẹ si fi ara nyin han bi ọkunrin: ẹ gba a si ọkan, ẹnyin alarekọja. Ẹ ranti nkan iṣaju atijọ: nitori emi li Ọlọrun, ko si si ẹlomiran, emi li Ọlọrun, ko si si ẹniti o dabi emi. Ẹniti nsọ opin lati ipilẹṣẹ wá, ati nkan ti ko ti iṣe lati igbani wá, wipe, Imọ mi yio duro, emi o si se gbogbo ifẹ mi. Ẹniti npe idì lati ila-orun wa: ọkunrin na ti o mu imọ mi ṣẹ lati ilẹ jijin wá: lotọ, emi ti sọ ọ, emi o si mu u ṣẹ; emi ti pinnu, emi o si ṣe e pẹlu.”—Isaiah 46:8-11.
29, 30. Bawo ni Jehofah ṣe di ete rẹ̀ mu gẹgẹ bi a ti sọ ọ ninu asọtẹlẹ na, li ọna wo li eyi si gba fun wa lokun?
29 Dajudaju Kirusi Nla na ara Persia wa lati ila-orùn gẹgẹ bi ẹiyẹ “idì” lati Persia si ila-orùn Babiloni ati lati ilẹ ti o jinna si ilu Isaiah, ilẹ Israeli.
30 Pẹlu iṣedede, ami ọla aṣẹ Kirusi Nla na jẹ ẹiyẹ idì ti a fi wura ṣe, ẹiyẹ “idì” kan, Jehofah si lo o gẹgẹ
bi ami Kirusi funrarẹ̀. Biotilẹjẹpe a sọ ọ ninu awọn ọrọ wọnyi ni eyiti o fẹrẹ to ọgọrun ọdun lọna meji tẹlẹ, ete Ọlọrun na ko jakulẹ. “Imọ” rẹ̀ duro, nipa lilo ti On lo Kirusi lati mu imọ Rẹ̀ ṣẹ lodisi Babiloni buburu. Jehofah ti sọ ọ, ani o tilẹ mu ki a kọ ọ silẹ fun itọkasi lọjọ iwaju; nigbati akoko rẹ̀ si de o ṣe ohun ti on sọ. O ti ṣe ete rẹ̀ niti Kirusi o si ti kede rẹ̀ nipasẹ woli rẹ̀, nigbati akoko rẹ̀ si to gan o mu ohun ti on ti pete wá si imuṣẹ yiyani-lẹnu. Awọn aṣeyọri wọnyi ninu itan ti o jẹ ti Ọlọrun asọtẹlẹ fun igbẹkẹle wa lagbara ninu idaniloju gbogbo awọn asọtẹlẹ miran ninu eyiti Jehofah ti fi lelẹ ohun ti on ti pinnu lati ṣe ni ibamu pẹlu “imọ” rẹ̀ funrarẹ.31. Asọtẹlẹ Esekieli wo, ti a koiti muṣẹ sibẹ, li o salaye ikọlu kan—lati ọwọ tani ati sori awọn wo?
31 Eyiyi jẹ otitọ niti asọtẹlẹ kan ti itan fihan pe koiti ni imuṣẹ sibẹ, ṣugbọn akoko fun imuṣẹ eyiti o ṣe kedere pe o nsunmọle, lati ṣẹlẹ ninu iran wa. Eyiyi jẹ asọtẹlẹ kan ti a fifunni nipasẹ woli Esekieli, ẹniti o gbe aiye li akoko kanna pẹlu woli Jeremiah. A rii ninu. ori kejidinlogoji ati ikọkandinlogoji Esekieli. O ni iṣe pẹlu ikọlu ti o nilati ṣẹlẹ lati ọwọ “Gogu ara Magogu!” ohun iyanu na. Gogu yi yio mu gbogbo orilẹ-ede aiye yi wá sinu ikọlu yi. Ikọlu jakejado aiye na li ao ṣe si iyoku awọn olusin Ọlọrun alàyè ati otitọ na. Pẹlu idasilẹ kuro ninu Babiloni Nla ti ode-oni ati imupadabọsipo ojurere Ọlọrun, iyoku olótọ yi ngbe ninu Paradise ti ẹmi larin aiye ẹlẹgbin ati oniwa ibajẹ na. Kini idi ti Ọlọrun Olodumare fi yọ̀da ki a ṣe iru ikọlu bẹ si awọn olusin Rẹ̀ funrarẹ̀? O sọ fun wa.
32, 33. Fun ete wo ni Ọlọrun fi jẹki Gogu kọlu awọn olusin Rẹ̀ ninu paradise wọn ti ẹmi loni?
32 Ni sisọ fun wa, Ọlọrun lò lọna apẹrẹ ilẹ Israeli igbanì ati awọn olugbe rẹ̀ ti a dá silẹ kuro lati Babiloni lati ṣapẹrẹ Paradise ti ẹmi eyiti a mu iyoku awọn olusin Rẹ̀ loni padabọ si. Nigbana, nigbati on mba Aṣaju
Buburu fun ikọlu agbaiye yi sori olotọ iyoku na ninu Paradise wọn ti ẹmi sọrọ, Ọlọrun Olodumare mu ki ete rẹ̀ ṣe kedere ni yiyọda ikọlu oníkà yi nipa sisọ pe:33 “Iwọ o si goke wá si awọn enia mi Israeli, bi awọsanma lati bo ilẹ; yio si ṣe nikẹhin ọjọ, emi o si mu ọ dojukọ ilẹ mi, [Heberu: ma’an] ki awọn orilẹ-ede ki o le mọ̀ mi, nigbati a o yà mi si mimọ ninu rẹ, niwaju wọn, iwọ Gogu.”—Esekieli 38:15, 16.
34, 35. Kini ete Ọlọrun ti a kede rẹ̀ ninu yiya ara rẹ̀ si mimọ niti Gogu?
34 Ko si ohun miran ti a tun le sọ kedere ju eyi lọ. Ete Jehofah ni lati ya ara rẹ̀ si mimọ́ niwaju gbogbo orilẹ-ede. Ni ibamu pẹlu gbogbo awọn iṣẹ rẹ̀ ti o ti kọja, On yio mu ete rẹ̀ ti kí yipada yi ṣẹ laipẹ si igba ti a wà yi, ninu iran wa. Lẹhinti on ti sọ bi on yio ti ṣe lo ọna iyanu ti o wa larọwọto rẹ̀ lati ja ogun ajaṣẹgun lodisi Gogu ati gbogbo ọmọ-ogun agbaiye rẹ̀ lori ilẹ aiye, Ọlọrun ete ti ki kuna wipe:
35 “Emi o si gbe ara mi leke, emi o si ya ara mi si mimọ; emi o si di mimọ loju ọpọlọpọ orilẹ-ede, nwọn o si mọ pe emi ni [Jehofah].”—Esekieli 38:23.
KINI AWA YIO ṢE NIPA RẸ̀?
36. Eṣe ti a fi nilati bere lọwọ ara wa boya a fẹ ki a fà wa lọ pẹlu awọn orilẹ-ede ti a nilati mu ki o mọ ẹniti Jehofah iṣe?
36 Mimu ki awọn orilẹ-ede aiye mọ̀ ẹniti On iṣe ko ni fihan pe nwọn jẹ olusin rẹ̀ lati yẹ fun èrè iye ainipẹkun. Kakabẹ, yio tumọsi iparun aiyeraiye fun awọn orilẹ-ede wọnni ti ntabuku si Ọlọrun! Eyini jẹ ọna onijamba fun kikẹkọ lati ni iriri ẹniti Ọlọrun otitọ na iṣe. On yio fihan awọn orilẹ-ede na ẹniti on iṣe gan. O ti di ọranyan fun U lati ṣe bẹ. Nitorina, ibere nla na ni, Awa funrawa ha fẹ lati wà ninu awọn orilẹ-ede wọnni ti ao fà sinu ikọlu na ti Ọta Nla fun Ọlọrun yio ṣe laipẹ, eyini ni, “Gogu ara Magogu”?
37. Dipo jijẹki awọn iwewe enia fun igbala ara-ẹni yí wa lọkan pada, ọna wo ni Owe 19:20, 21 gbani nimọran?
37 Ninu gbogbo iwewe wọn fun titun ipo aiye ṣe, awọn orilẹ-ede ko ronu nipa Ọlọrun otitọ ati alayè Owe 19:20, 21: “Fetisi ìmọ ki o si gba ẹkọ, ki iwọ ki o le gbọ́n ni igbẹhin rẹ. Ete [Heberu: mahha.sha-bhoth’] pupọ li o wà li aiya enia; ṣugbọn igbimọ [Jehofah], eyini ni yio duro.” O gbọdọ jinna si ọkan wa lati mu awọn iwewe enia ati orilẹ-ede dojukọ igbimọ Jehofah.
na, ni ibamu pẹlu ete Rẹ̀ gẹgẹ bi a ti fihan kedere ninu Bibeli Mimọ, Ọrọ rẹ̀ ti a kọwe rẹ̀ silẹ. Awọn iwewe wọn ha dabi ohun ti o dara fun wa bi? Awa yio ha jẹki awọn iwewe wọn yí wa lọkan pada ki a si darapọ ninu itilẹhin iwọnyi, ki a si tipa bayi gbẹkẹle igbala ara-ẹni lati ọwọ enia? Bi a ba fẹ pinnu fun ara wa ohun ti a nilati ṣe, awa yio jẹ ọlọgbọn lati ronu ki a si fi sọkan ohun ti ọlọgbọn ọkunrin igbánì ti a misi wi, ninu38. Eṣe ti nini igbẹkẹle ninu Jehofah ko le yọrisi ijakulẹ pẹlu awọn orilẹ-ede ati enia?
38 Eṣe ti a fi nilati jiya ijakulẹ pẹlu awọn orilẹ-ede si ipalara wa ailopin? Ẹ jẹki a gbẹkẹle Jehofah tọkantọkan. “Nitori ti o sọrọ, o si ti ṣẹ, o paṣẹ, o si duro ṣinṣin. [Jehofah] mu imọ awọn orilẹ-ede di asan: o mu arekereke awọn enia ṣaki. Imọ [Jehofah] duro lailai, iro inu rẹ̀ lati irandiran. Ibukun ni fun orilẹ-ede na, Ọlọrun ẹniti [Jehofah] iṣe; ati awọn enia na ti o ti yàn ṣe ini rẹ̀.”? (Orin Dafidi 33:9-12) Leralera li o ti fihan pe o jẹ otitọ ni igba atijọ, yio si fihan pe o jẹ otitọ laitase laipẹ si igba ti a wà yi, pe “Ko si ọgbọn, ko si imoye, tabi igbimọ si [Jehofah]. A mura ẹṣin silẹ de ọjọ ogun: ṣugbọn iṣẹgun lati ọwọ [Jehofah] ni.”—Owe 21:30, 31.
39. Iru ete wo ni Jehofah nilati ni fun awọn wọnni ti nwá ododo rẹ̀, esitiṣe?
39 Wiwo ipo aiye araiye pẹlu otitọ ọkan mu u dá wa loju pe gbogbo wa li o nfẹ igbala. Ohun ti awa enia olótọ-ọkàn nfẹ ni igbala! Eyi ko le wá lati ọwọ enia funrarẹ̀ lai. Awa gbọdọ gba pe “igbala nti ọdọ [Jehofah] wa.” Niwọnbi “Oluwa ti ṣe ohun gbogbo fun ipinnu rẹ̀: nitotọ, awọn enia buburu fun ọjọ ibi,” kini o nilati jẹ ete Oluwa Ọlọrun fun awọn wọnni ti ko buru, awọn wọnni ti nwá ododo Rẹ̀? Laisi aniani ete onifẹ! (Owe 16:4, The New American Bible) Dajudaju araiye wà ninu ete rere Ẹlẹda onifẹ na.
40. Kini nilati jẹ ete wa bi awa ba fẹ de ibikán ninu iye ainipẹkun, esitiṣe?
40 Elẹda na ki iṣe Ọlọrun kan ti ko li ete. Awa ti a jẹ ẹda rẹ̀ ko gbọdọ ṣe alaini ete pẹlu! Nigbana, kini ete ti awa yio má lepa? Eyi: Lati mu igbesi aiye wa. wà ni ibamu pẹlu ete rere Jehofah Ọlọrun. Ohun miran ti o ga ju eyi ko si ti a nilati má lepa. Nipa ṣiṣe eyi, dajudaju awa yio má sunmọ ibikan—gbigbadun iye ainipẹkun wa. Li ọna bayi igbesi aiye wa isisiyi ko ni jẹ ikuna, nitoripe ete Ọlọrun ko le kuna lai. Pẹlu eyi niwaju wa, awa layọ nisisiyi ninu ṣiṣe ayẹwo “ete aiyeraiye” Ọlọrun ti On ṣe niti Messiah, Ẹni-ororo rẹ̀.
[Awọn Alaye Isale Iwe]
^ ìpínrọ̀ 5 Wo itumọ William Tyndale (1525 ati 1535 C.E.); Geneva Bible (1560 ati 1562 C.E.); Bishop’s Bible (1568 ati 1602).
^ ìpínrọ̀ 6 Wo Hugh J. Schonfield’s Authentic New Testamemt (1955 C.E.), eyiti o lo “iwewe igba pipẹ.” The Jerusalem Bible (1966 C.E.) ka pe: “iwewe ti on ti ni lati igba aiyeraiye.” Itumọ lati ọwọ-George N. LerFevre (1928 C.E.) ka pe: “iwewe igba pipẹ ti on pete nipasẹ Ẹni-ororo na.” Ọrọ na “iwewe” ko farahan ninu King; James Authorised Version ati Bibeli American Standard Version, Ninu Roman Catholic Douay Version ọrọ na “iwewe” farahan ninu Esekieli 4:1; 43:11 ati 2 Macabees 2:29.
^ ìpínrọ̀ 9 Fun ipo atẹhinwa ati ti ode oni ti a mu lori ọrọ na, wo ẹsẹ 14-19 ninu akori ti o ṣaju ti a npe ni “Ọmọ Enia” (Psalmu 8:4) ti a tẹjade ninu ìtẹjade ti April 1, 1930, The Watch Tower (oju ìwe 101, 102). Ṣakiyesi ni pataki ẹsẹ 16.
^ ìpínrọ̀ 11 Wo Theological Dictionary of the New Testament, Volume VIII, lati ọwọ Gerhard Friedrich. (English translation), oju iwe 165, 166, labẹ “Majẹmu Titun.”
^ ìpínrọ̀ 12 The Book of Books, lati ọwọ Lutterworth Press (1938).
^ ìpínrọ̀ 12 Young’s Literal Translation of the Holy Bible.
^ ìpínrọ̀ 12 The New English Bible (1970).
^ ìpínrọ̀ 12 The New American Bible (1970).
^ ìpínrọ̀ 12 An American Translation; A New Translation of the Bible, lati ọwọ James Moffatt (1922); The Westminster Version of the Sacred Scriptures (1948); The Bible in Living English (1972); Elberfelder Bibel (German); The New Testament in Modern Speech, lati ọwọ R. F. Weymouth (Eleventh Impression); The New Testament - A New Translation, by Ronald Knox (1945); Revised Standard Version, (1952); American Standard Version (1901); English Revised Version (1881); King James Authorized Version (1611); New World Translation of the Holy Scriptures (1971).
^ ìpínrọ̀ 14 Lori “katà pro’the-sin ton ai-o’non” ninu Efesu 3:11, a ka pe: “Ni ibamu pẹlu ete awọn igba-aiye, eyini ni, ni ibamu pẹlu ete ti Ọlọrun ni lati awọn igba aiye (lati igba ibẹrẹ titi de imuṣẹ ete na); nitoripe tẹlẹtẹlẹ [ṣaju ki a to da aiye] a ti ṣe e, i. 3, ṣugbọn lati ibẹrẹ igba aiye a fi i pamọ ninu Ọlọrun, ẹsẹ 9 . . . Awọn miran, laiṣe dédé, gbà a gẹgẹ bi: ete na nipa oniruru igba aiye, ni ibamu pẹlu eyiti, eyini ni, Ọlọrun li akọkọ ko yan awọn enia kankan, lẹhinna o yan awọn Ju, nikẹhin o pe awọn Ju ati awọn Keferi sinu ijọba Messiah; nitoripe kiki ete kanṣoṣo na ni, eyiti a muṣẹ ninu [Messiah], ti a sọrọ nipa rẹ̀.”—Critical and Exegetical Hand-Book to the Epistle to the Galatians—Ephesians lati ọwọ H. A. W, Meyer, Th.D., itumọ Gẹsi, 1884, oju iwe 416, ẹsẹ 1.
^ ìpínrọ̀ 16 “Eyiti o pọ julọ ninu awọn ti ode oni li o tẹle Rashi ni titumọ ‘Emi yio jẹ ohun ti emi yio jẹ’; eyini ni, ko si awọn ọrọ ti o le ṣe akopọ gbogbo ohun ti On yio jẹ fun awọn enia Rẹ̀, ṣugbọn iṣotitọ Rẹ̀ titilai ati anu rẹ̀ ti ki yipada yio ma fi ara wọn han siwaju ati siwaju ninu itọsọna Israeli. Idahun ti Mose ri gba ninu awọn ọrọ wọnyì nipa bayi ṣe dede pẹlu, ‘Emi yio gbala li ọna ti emi yio gbala.’ O jẹ lati mu da awọn ọmọ Israeli loju otitọ idande, ṣugbọn ko fi ọna na han.”—Alaye isalẹ iwe lori Eksodu 3:14, The Pentateuch, and Haftorahs, lati ọwọ Dr. J. H. Hertz, C. H., Soncino Press, London, 1950 C.E.
[Ibeere]
APOTI
“WRITE DOWN THE VISION AND MAKE IT PLAIN UPON TABLES, THAT EVERY ONE MAY READ IT FLUENTLY.” HABAKKUK 2:2. CHART OF THE AGES.
ILLUSTRATING THE PLAN OF GOD FOR BRINGING MANY SONS TO GLORY, AND HIS PURPOSE—“In regard to an administration of the fulness of the appointed times, to reunite all things under one Head, even under the Anointed One; the things in heaven and the things on earth—under Him.”—Eph. 1:10—Diaglott.