Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọlọrun Fi Ete Rẹ̀ Lelẹ fun Ọkunrin ati Obirin

Ọlọrun Fi Ete Rẹ̀ Lelẹ fun Ọkunrin ati Obirin

Ori 4

Ọlọrun Fi Ete Rẹ̀ Lelẹ fun Ọkunrin ati Obirin

Nigbati Adamu ọkunrin ekini na nikan wà ninu Paradise Igbadun pẹlu kiki awọn ẹda rirẹlẹ lori ilẹ aiye gẹgẹ bi ẹlẹgbẹ rẹ̀, Ọlọrun ko sọ ohunkohun fun u nipa jijẹ ti Adamu yio jẹ baba fun iran enia. Ṣugbọn Ọlọrun ní eyi li ọkan. Eyiyi ni ete Rẹ̀ nipa ilẹ aiye. Laipẹ o fi ete atọrunwa yi han fun enia

2, 3. (a) Bawo li Ọlọrun ṣe pete lati mu idile enia jade? (b) Eṣe ti ko fi si oluranlọwọ ti o yẹ fun eyi lárin awọn ẹda ti o rẹlẹ si enia?

2 Ọlọrun ko pete lati fi enia kún ilẹ aiye li ọna kanna ti on gba fikun ọrun, nipa dida wọn táràtà laisi ilo igbeyawo. Ọlọrun pete pe ki ọkunrin na Adamu gbeyawo pẹlu ẹnikeji ti o yẹ, ki o si fojusọna fun jijẹ baba. Ero Ọlọrun lori ọran na li a kọ silẹ ninu Genesisi 2:18, eyiti o sọ fun wa pe: “[Jehofah] Ọlọrun si wipe, ko dara ki ọkunrin na ki o nikan ma gbe; emi o ṣe oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u”

3 Ọlọrun ti da gbogbo awọn ẹda rirẹlẹ lori ilẹ aiye ṣaju iṣẹda enia o si yatọ si iṣẹda enia. Nipa bayi awọn ẹda rirẹlẹ si enia, ẹja, awọn ẹda abiyẹ, awọn ẹranko ti nrako, ki iṣe “iru!” ti enia. Nwọn le mu ọmọ jade olukuluku “ni iru tirẹ̀” (Genesisi 1:21, 22, 25) Nwọn ko le sowọpọ pẹlu enia ni mimu iru enia jade. Eyiyi li a nilati ri kedere lẹhinti Ọlọrun ti fi awọn ẹda rirẹlẹ ori ilẹ aiye han Adamu. Nitorina ipinnu ti o lọgbọn ninu, lẹhinti a ti mu Adamu mọ gbogbo awọn ẹranko ni pe: “Ṣugbọn fun Adamu a ko ri olunranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u”—Genesisi 2:19, 20.

4 Sibẹ o si jẹ “ọjọ” iṣẹda kẹfa, nitorina Ọlọrun ko rú ofin eto ọjọ isimi kankan nipa biba a lọ lati ṣiṣẹ iṣẹda lori ilẹ aiye. Nigbana, bawo li on ṣe dá oluranlọwọ kan fun Adamu ti o dabi rẹ̀? Ọpọ ẹgbẹrun ọdun ṣaju ki ọgbọn iṣegun ode oni to ṣe awari awọn akunnilorun ati adín-irora-kù fun ṣiṣe iṣẹ abẹ laisi irora, Ọlọrun ṣe iṣẹ abẹ kan fun Adamu ọkunrin ekini laisi irora. “[Jehofah] Ọlọrun si mu orun ijika kun Adamu, o si sùn: o si yọ òkan ninu egungun-iha rẹ̀, o si fi ẹran dí ipo rẹ̀: [Jehofah] Ọlọrun si fi egungun-iha ti o mu ni iha ọkunrin na mọ obirin, o si mu u tọ ọkunrin na wa. Adamu si wipe, Eyiyi li egungun ninu egungun mi: Obirin (“Ish·shah’) li a o má pe e, nitori ti a mu u jade lati ara ọkunrin (”ish”) wá”—Genesisi 2:21-23.

5. Nipa bayi, bawo li a ṣe mu iṣọkan ninu ẹran ara jade ninu gbogbo idile enia?

5 Gẹgẹ bi a ti ṣe sọ fun Adamu bi a ti ṣe mu obirin ekini jade lati inu ọkan ninu awọn egungun-iha rẹ̀ (pẹlu awọn ohun ti nmu ẹjẹ pọ si i ninu egungun rẹ̀), on le pe e ni egungun ninu egungun rẹ̀ ati ẹran ara ninu ẹran-ara rẹ̀ bi o ti to. On ni idi ti o tobi ju lati rò pe on jẹ apakan rẹ̀ nitoripe ara on tikararẹ̀ ti ni ipa ninu iṣẹda rẹ̀ lati ọwọ Ọlọrun. Gẹgẹ bi o ti tọ laitase a le sọ ni ẹgbẹgbẹrun ọdun lẹhinna ni ile ẹjọ Areopagu ni Ateni, Greece pe: “O [Ọlọrun] si ti fi ẹjẹ kanna dá gbogbo orilẹ-ede lati tẹdo si oju agbaiye” (Iṣe 17:26) Nipa bayi a ri jijẹ ara kanna ninu gbogbo idile enia, iru eyiti ki ba ti si bi o ba jẹ pe Ọlọrun dá obirin ekini lati inu erupẹ ilẹ li ọna ti o yatọ si Adamu ọkunrin ekini.

6. Gẹgẹ bi awọn ọrọ Ọlọrun ti wi, bawo ni idile enia yio ṣe tankalẹ?

6 Lẹhinti o ti sọrọ nipa igbeyawo ọkunrin ekini ati obirin ekini yi ninu Paradise, akọsilẹ. atọrunwa na tẹsiwaju lati wipe: “Nitorina li ọkunrin yio ṣe ma fi baba on iya rẹ̀ silẹ, yio si fi ara mọ aya rẹ̀: nwọn o si di ara kan” Nitori ọna ti a gba da obirin na, Adamu ati aya rẹ̀ jẹ “ara kan? ṣaju ki nwọn tilẹ to ni ibalopọ papọ. Igbeyawo ọmọ Adamu ati aya rẹ̀ so wọn papọ ninu ibalopọ takọtabo ati ni pataki li ọna bayi nwọn di “ara kan” nigba ekini. Fifi baba ati iya silẹ lati fi ara mọ aya rẹ̀ yio tumọsi pe ọkunrin ti o ṣẹṣẹ gbeyawo na yio gbe idile tirẹ̀ kalẹ. Li ọna bayi idile enia yio tankalẹ.

7. Eṣe ti Adamu ati aya rẹ̀ ko fi tiju nigbati nwọn ri bi a ti ṣe da wọn?

7 Ijẹpipe ailẹṣẹ, ọkàn mimọ gára wà nigbana, ninu Paradise Edeni. Eyiyi lia jẹri si ninu ọrọ Genesisi 2:25 pe: “Awọn mejeji si wà ni ihoho, ati ọkunrin na ati obirin rẹ̀, nwọn ko si tiju” Nwọn ni ẹri-ọkan rere si Ọlọrun ati si ara wọn.

8, 9. (a) Nipa bayi, tani da ẹya takọtabo, fun ete wo si ni? (b) Bawo ni ohun ti Ọlọrun sọ fun Adamu ati Efa lati ṣe ṣe fi otitọ yi han?

8 Nihin, nisisiyi, ni ibiti akọsilẹ na ninu Genesisi 1:27 ti sopọ mọ ọ, ninu itolẹsẹsẹ ti o yẹ, nisisiyi ti a ti ni ọkunrin ati obirin ninu iran Paradise. Akọsilẹ na kà pe: “Bẹli Ọlọrun da enia li aworan rẹ̀, li aworan Ọlọrun li o da a; ati akọ ati abo li o da wọn”? Gan gẹgẹ bi o ti jẹ ṣaju eyi, akọ ati abo ti wà larin awọn ẹda rirẹlẹ lori ilẹ aiye, ki awọn wọnyi ba le ma mu “iru wọn” jade, bẹ gẹgẹ li o ri pe nigbati a da obirin, akọ ati abo wà ninu iru enia. Ọlọrun li o da ẹya takọtabo, ṣugbọn fun ete ibimọ. Otitọ pataki yi li a fihan ninu ohun ti Ọlọrun sọ nisisiyi fun ọkunrin ekini ati obirin ekini lati ṣe.

9 Ọlọrun si sure fun wọn. Ọlọrun si wi fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ki ẹ si ma rẹ̀, ki ẹ si gbilẹ, ki ẹ ṣe ikawọ rẹ̀; ki ẹ si má jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ohun aláyè gbogbo ti nrako lori ilẹ”—Genesisi 1:28.

10. Bẹ gẹgẹ, kini ipo ikẹhin fun oju agbaiye ti Ọlọrun pete rẹ̀?

10 Ọlọrun sure fun ọkunrin ati obirin na ni ibẹrẹ igbesi aiye tọkọtaya wọn ninu Paradise. Igbadun. Awọn ironu rẹ̀ ati ọrọ rẹ̀ jẹ eyiti o darajulọ fun wọn. Nipa awọn ọrọ rẹ̀ si wọn, Ọlọrun fihan ohun ti ete rẹ̀ jẹ fun araiye ati ilẹ aiye. Ọlọrun pete pe awọn ọmọ ọkunrin ekini ati obirin ekini yi li a nilati fi kun ilẹ aiye yi. Ki iṣe eyi nikan, ṣugbọn pẹlu pe gbogbo ilẹ aiye na eyiti idile enia yi yio kun ni a nilati ṣe ikawọ rẹ̀. Ṣe ikawọ rẹ̀ de ipo wo? De ipo Paradise ninu eyiti ọkunrin ati obirin na ba ara wọn. Eyiyi tumọsi pe gbogbo ilẹ aiye li a nilati sọ di ẹlẹwa ki a si sọ ọ di ibi gbigbe nipa mimu awọn álà Paradise na gborò ti Ọlọrum ti gbin titi ila-orùn yio fi pade iwọ-orùn ti ariwa yio si pade gusu—si gbogbo orilẹ-ede ati si gbogbo erekuṣu okun. Ko gbọdọ si fifunpọ awọn enia ni Paradise ilẹ aiye na, ṣugbọn awọn enia yio má ba a lọ lati bimọ titi gbogbo ilẹ aiye ti a ṣe ikawọ rẹ̀ yio fi kun pẹlu irọrun. Nwọn ko nilati pa awọn ẹda rirẹlẹ run lori ilẹ aiye, ṣugbọn nwọn nilati fi wọn sabẹ itẹriba—sabẹ iṣakoso onifẹ.

11, 12. (a) Eṣe ti a ko fi gbọdọ mu oju kuro ninu ete Ọlọrun fun enia ati ilẹ aiye? (b) Bawo li awa ṣe le mu igbesi aiye wa ní ete ninu, pẹlu anfani pipẹ titi fun wa?

11 Ninu awọn ọrọ ti Ọlọrun. fi sure ti o si pa wọn laṣẹ, Adamu ati aya rẹ̀ ha ri iran ete ologo ti Ọlọrun ni fun wọn ati fun ile wọn, ilẹ aiye bi? Awa ha ri i loni bi? Awa loni ha loye ete akọkọ ti Ọlọrun Ẹlẹda ni fun ọkunrin ati obirin ati ile wa, ilẹ aiye? Ete rẹ̀ ti a sọ pẹlu irọrun tobẹ, ko si ṣoro fun enia olotọ ọkàn lati dimu.

12 Bi awa ba loye rẹ̀, nigbana ẹ maṣe jẹki a padanu rẹ̀, nitori nigbana awa yio ṣubu sinu idarudapọ isin ati iṣina. Wiwa enia lori ilẹ aiye ki iṣe akọsẹbaa ko si pete rẹ̀ lati wa lofo. Ọlọrun mọmọ fi ọkunrin ati obirin si ori ilẹ aiye fun ete kan, ete yi li on si fihan awọn enia obi wa akọkọ. Lẹhinti Adamu ati aya rẹ̀, ẹniti on pe ni Efa, ti di ẹniti a sọ fun ti a si pa laṣẹ, o jẹ anfani wọn ọlọla ati onibukun lati sọ ete Ọlọrun di ete wọn ninu igbesi aiye. Eyi yio bere fun igbọran wọn si Ọlọrun. Lẹhinna, igbọran yio si yọrisi iye aiyeraiye ninu ayọ pipẹ lori Paradise ilẹ aiye, fun Adamu ati Efa onigbọran ati fun gbogbo ọmọ wọn onigbọran ninu gbogbo igun mẹrẹrin ilẹ aiye ti a ti ṣe ikawọ rẹ̀. Nitorina igbesi aiye di ohun ti o ni ete ninu fun Adamu ati Efa, o si le ni ete ninu fun wa —gẹgẹ bi ete Ọlọrun ti kí kuna.

13. Ese ti ko fi gbọdọ si pipa ẹda aláyé kankan ninu Paradise, ati aibẹru ọwọn onjẹ fun ilẹ aiye ti a kún?

13 Ọlọrun ko fi si iwaju Adamu ati Efa ibẹru aito onjẹ kankan bi idile enia ti ndi pupọ” Gẹgẹ bi Baba onifẹ o ṣe ipese ti o pọ to fun ilẹ aiye ti o kun fun enia ọmọkunrin ati ọmọbirin rẹ̀. Ko si nilati si idi fun pipa ẹda aláyé kankan ninu Paradise na. Ọlọrun tọkasi awọn otitọ wọnyi, nitori a kà pe: Ọlọrun si wipe, kiye si i, Mo fi eweko gbogbo ti o wà lori ilẹ gbogbo ti nso eso fun nyin, ati igi gbogbo ninu eyiti iṣe igi eleso ti nso; ẹnyin ni yio má ṣe onjẹ fun. Ati fun gbogbo ẹranko, ilẹ ati fun gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ohun gbogbo ti o nrako lori ilẹ, ti iṣe aláye [gẹgẹ bi ọkàn (nephesh) kan], ni mo fi eweko tutu gbogbo fun li onjẹ o si ri bẹ”—Genesisi 1:29, 30.

14. (a) Ni afikun si gbolohun ọrọ Ọlọrun ti o kún na lori onjẹ, kini ikaléwọ lori onjẹ ti a mbere sibẹ? (b) O yẹ ki Adamu ati Efa wà láyè nipa kini, ni afikun si onjẹ ti ara?

14 Nihin li a ri gbolohun ọrọ kan ti o gbérò nipa ohun ti araiye nilati jẹ, gbolohun ọrọ kan ti Adamu ati Efa gbọ lati ọdọ Ọlọrun. Nitorina o sọrọ nipa “igi gbogbo ninu eyiti iṣe igi eleso” Ki iṣe nihinyi li akoko na lati ṣe ofintoto, nitoripe, ninu gbolohun ọrọ ti on ti sọ fun Adamu nikan, Ọlọrun ti fi ikaléwọ̀ sori jijẹ ninu igi imọ rere ati buburu. (Genesisi 2:16, 17) O kere o pọ fun akoko diẹ eso igi ti a kaléwọ̀ yi ko nilati jẹ onjẹ fun Adamu ati Efa. Biotiwukiori, onjẹ pupọ li o wà lati jẹ fun gbigbe ẹmi ro, laisi pe nwọn jẹ pẹlu lati inu igi imọ rere ati buburu. Ani pẹlu gbogbo ọpọlọpọ onirúiru onjẹ ninu Paradise, o jẹ otitọ nipa Adamu ati Efa gẹgẹ bi o ti jẹ otitọ nipa awọn ayanfẹ enia Jehofah ni eyiti o ju ẹgbẹrun ọdun lọna meji lẹhinna: “Enia ko ti ipa onjẹ nikan wà láyé, bikoṣe nipa gbogbo ọrọ ti o ti ẹnu [Jehofah] jade li enia wa laye” (Deuteronomi 8:3) Bi Adamu ati Efa ba pa ọrọ aṣẹ ti Jehofah Ọlọrun pa mọ, wọn yio wa láye titi lai pẹlu idile wọn ninu Paradise ti o kari aiye.

OPINỌJỌIṢẸDA KẸFA

15. Ni opin “ọjọ” iṣẹda kẹfa, bawo ni iṣẹda ilẹ aiye ṣe ri si Ọlọrun?

15 Nipa bayi ni akoko ti Ọlọrun sami si awọn ọran ilẹ aiye li a mu wa si gbangba gẹgẹ bi a ti ṣapejuwe, pẹlu lile ṣéṣe yiyanilẹnu ti o mbẹ niwaju gẹgẹ bi ete Ọlọrun. Bi a ti nwo ipo na, pẹlu ilẹ aiye nisisiyi ti o ni awọn ẹda enia ati ẹranko ninu ti o nyika orùn ati pẹlu oṣupa ti o nyika ilẹ aiye, bawo li o ti ri si wa? Ero wa ko gbọdọ yatọ si ti Ọlọrun, nipa eyiti a ka pe: “Ọlọrun si ri ohun gbogbo ti o dá, si kiyesi i, daradara ni. Ati aṣalẹ ati owurọ o di ọjọ kẹfa”—Genesisi 1:31.

16. Kini ti nilati jẹ iṣarasihuwa ’’awọn irawọ owurọ” na ati “awọn ọmọ Ọlọrun” nigbati nwọn ri ilẹ aiye li opin “ọjọ” kẹfa?

16 Jehofah, gẹgẹ bi Ọlọrun ilọsiwaju, ti bẹrẹsi tẹsiwaju lọna itolẹsẹsẹ, letoleto. Si wo itolẹsẹsẹ ti o lọgbọn ninu lati ọdọ Rẹ̀ wa! Pẹlu dida Adamu ati Efa ibukun atọrunwa lori wọn, opin de si “ọjọ” iṣẹda kẹfa Ọlọrun nipa mimura ilẹ aiye silẹ fun ibugbe awọn ọmọ Ọlọrun lori ilẹ aiye. Bi, nigba dida ilẹ aiye lasan, awọn irawọ owurọ jumọ kọrin pọ, ti gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun nho iho ayọ,“ wo awọn ọrọ idunnu ati iyin ti awọn “ọmọ Ọlọrun” wọnyi ti nilati sọ ni opin ọjọ iṣẹda kẹfa nigbati nwọn ri ilẹ aiye na nisisiyi ni ipo imurasilẹ ni kikun ati tọkọtaya enia pipe ti ngbe lori rẹ̀—Jobu 38:7; Genesisi 1:28.

17. Loju aṣeyọri Ọlọrun si opin “owurọ” “ọjọ” kẹfa, ibere wo li o dide nipa iye awọn ’ọjọ” iṣẹda?

17 “Owurọ! ọjọ” iṣẹda kẹfa dopin pẹlu aṣeyọri ologo atọrunwa. Iyipo awọn “ọjọ” iṣẹda yio dopin pẹlu ti ẹkẹfa bi? “Ọjọ” kẹfa dopin kiki pẹlu ipilẹ ti a gbe kalẹ ninu Adamu ati Efa fun kikun gbogbo ilẹ-aiye. “Ọjọ” iṣẹda miran, “ọjọ” keje, yio ha wa ni opin ’’owurọ” na eyiti gbogbo ilẹ aiye yio kun fun idile enia ki o si di Paradise jakejado aiye?

ỌJỌIṢẸDA KEJE BẸRẸ, NI NKAN BI 4026 B.C.E.

18. Ni biba ọgbọn mu, pẹlu opin wo li ọjọ iwaju li a gbọdọ fi aye silẹ fun ’’ọjọ’’ iṣẹda miran?

18 Ete Ọlọrun fun ilẹ aiye li a koiti ṣe li aṣeyọri ni kikun ni opin “ọjọ” iṣẹda kẹfa. O ku ibere na, Ọlọrun ha le ṣe aṣeyọri ete yi, ni pataki nisisiyi ti on mba awọn ẹda enia lo ẹniti o li agbara ifẹ ara-ẹni ẹniti on si fi silẹ li ominira lati yan ipa ọna wọn lori ilẹ aiye, yala ni ibamu pẹlu ete Ọlọrun tabi ni ilodi si i? O lọgbọn ninu, nigbana, pe “ọjọ” iṣẹda miran, “ọjọ” keje, li a nilati yọda fun, ninu eyiti a nilati mu ki ilẹ aiye na di eyiti o kun fun iran enia pipe, ki gbogbo wọn si gbepọ ninu ifẹ ati alafia ki gbogbo wọn si sọ ede kanna ninu Paradise agbaiye kan. Opin iru “ọjọ” iṣẹda bẹ le fojuri ete Ọlọrun ti a muṣẹ pẹlu iṣẹgun, ni idalare Rẹ̀ gẹgẹ bi Elẹda ati Ọba Alaṣẹ Agbaiye.

19. (a) Eṣe ti a fi gbọdọ pe ekeje ni ọjọ “iṣẹda?” kan? (b) Kini Ọlọrun ṣe niti “ọjọ keje” na?

19 Nitotọ Ọlọrun mu ki ete rẹ̀ di mimọ̀ ni kikun. Dajudaju o bere fun “ọjọ” keje iṣẹda kan. Pipe ti awa npe e ni ọjọ “iṣẹda? kan ko tumọsi pe Ọlọrun nba a lọ lati da awọn nkan ori ilẹ aiye ni “ọjọ” iṣẹda keje, ṣugbọn pe ko ṣe iyasọtọ kuro ninu ’’awọn ọjọ” iṣẹda mẹfa ti o ti wa tẹlẹ, ati pe o jẹ ọkan na ninu gigun akoko pẹlu “awọn ọjọ’’ wọnni ti o ti wa tẹlẹ. Kini Ọrọ Ọlọrun funrarẹ̀ wi nipa rẹ̀?

“Bẹ li a pari ọrun on aiye, ati gbogbo ogun wọn, Ni ijọ keje Ọlọrun si pari iṣẹ rẹ̀ ti o ti nṣe; o si simi ni ijọ keje kuro inu iṣẹ rẹ̀ gbogbo ti o ti nṣe. Ọlọrun si busi ijọ keje, o si yà a si mimọ; nitori pe, ninu rẹ̀ li o simi kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo ti o ti bẹrẹ si iṣe.—Genesisi 2:1-3.

20. Bawo li a ṣe mọ boya Genesisi 2:1-8 nsọrọ nipa ọjọ oni-wakati-mẹrinlelogun tabi igba iṣẹda kan ti o ṣì mba a lọ?

20 Ki a maṣe gbojufo otitọ na da pe akọsilẹ “ọjọ” iṣẹda keje yi ko pari pẹlu awọn ọrọ na ti o sọ pato pe “ọjọ” iṣẹda kan dopin pẹlu aṣalẹ ati owurọ. Genesisi 2:3 ko ṣe afikun awọn ọrọ na: “Ati aṣalẹ ati owurọ o di ọjọ keje” Ikuna iru awọn ọrọ ti nfi opin si awọn ọrọ bẹ lati farahan fihan pe “ọjọ” iṣẹda keje koiti dopin sibẹ li akoko na ti Mose pari kikọ Pentateuch tabi “awọn iwe marun”? akọkọ ninu Bibeli, ni ọdun 2553 Anno Mundi tabi 1473 B.C.E. Sibẹ lẹhinna Dafidi onipsalmu na sọrọ nipa wiwọ inu isimi Ọlọrun, ninu Psalmu 95:7-11, tabi ni nkan bi ọdun 2989 A.M. tabi 1037 B.C.E. Eyiyi fihan pe Genesisi 2:1-3, ni sisọrọ nipa ọjọ isimi Ọlọrun, ko sọrọ nipa ọjọ oni-wakati-mẹrinlelogun, ṣugbọn o nsọrọ nipa ‘’ọjọ” iṣẹda kan ti o gùn bakanna gẹgẹ bi ọkọkan ninu “awọn ọjọ” iṣẹda ti o ti wà ṣaju. Nitorina “ọjọ keje” iṣẹda koiti dopin ani sibẹsibẹ.

21. Ipo wo lori ilẹ aiye li o fihan pe araiye ni gbogbogbo koiti wọ inu pipa “ọjọ keje” ọjọ isimi Ọlọrun mọ?

21 Bẹ gẹgẹ, a koiti ri Paradise Edeni ki o gborò de gbogbo ilẹ agbaiye yika ki idile enia pipe, ti ki ku ki o kún ibi gbogbo. Kakabẹ, awọn ẹranko, ẹiyẹ ati ẹja li a npa kuro, awọn alagbara gigagiga ilẹ aiye, ti nwọn ti mura awọn afọnja oloro silẹ ati awọn ohun ija ipanirun miran, nhalẹ lati ké gbogbo araiye kuro ki nwọn si fi ilẹ aiye agbaiye silẹ lofo laisi olugbe. Dajudaju araiye li apapọ, bẹni, ani ẹgbẹ awọn aṣaju isin wọnni ti nwọn nsọ pe nwọn nsin Ọlọrun Bibeli Mimọ, koiti wọ inu isimi Ọlọrun, ki mwọn si pa “ọjọ isimi” iṣẹda rẹ̀ mọ. Nisisiyi o si ti fẹrẹ to ẹgbáta ọdun lati igbati a ti da enia!

22. Bawo ni ẹsẹ ti o tun tẹle e (Genesisi 2:4) ṣe fihan pe Ọlọrun ko sọrọ nipa ọjọ oni-wakati-mẹrinlelogun?

22 Pe akọsilẹ na ninu Genesisi 2:1-3 ko sọrọ nipa “ọjọ keje” gẹgẹ bi ọjọ oni-wakati-mẹrinlelogun ṣe kedere lati inu lilo ti a lo ọrọ na “ỌjỌ” ninu ẹsẹ ti o tẹle e gan. Nibẹ ninu Genesisi 2:4, a kọ ọ pe: “Itan ọrun on aiye ni wọnyi nigbati a dá wọn, li ọjọ ti [Jehofah] Ọlọrun da aiye on ọrun. “Ọjọ” na ni “awọn ọjọ” iṣẹda mẹfa ninu, gẹgẹ bi a ti ṣapejuwe rẹ̀ ninu Genesisi, ori ekini.

23 Lati inu ipo bi awọn ọran araiye ti ri ninu ọgọrun ọdun lọna ogun C.E. yi, ko si ohunkohun ti o tun le ṣe kedere ju pe imuṣẹ ete Ọlọrun li opin “ọjọ” iṣẹda keje ṣi mbẹ niwaju wa sibẹ. Ni ibẹrẹ “ọjọ keje yi ni nkan bi ẹgbáta ọdun sẹhin Ọlọrun “si busi ijọ keje, o si ya a si mimọ” Gẹgẹ bi itan araiye ti wi lati ẹgbẹrun ọdun mẹfa wá, koiti jẹ ọjọ ti a busi fun gbogbo iran enia. O han gbangba pe, ibukun Ọlọrun lori “ọjọ” keje yi ti ṣiṣẹ diẹ nitori gbogbo araiye.

24 Biotilẹjẹpe Ọlọrun ya a si mimọ tabi sọ ọ di mimọ, diẹ ninu araiye li o nya a si mimọ, sọ ọ di mimọ, nwọn si ti wọ inu isimi Ọlọrun nipa ti ẹmi. Dajudaju Ọlọrun yio fihan li opin “ọjọ” iṣẹda keje pe ibukun on lori ọjọ na ti ni itoye tootọ fun araiye. On yio fihan pe “ọjọ keje” yi ti ni iyasimimọ́, ijẹmimọ, wiwa ni mìmọ, ati pe “isimi” rẹ̀ nipa idaniloju nipa aṣeyọri ete rẹ̀ li a ko dilọwọ. Laika sisimi ti on simi kuro ninu iṣẹ iṣẹda rẹ̀ lori ilẹ aiye si li opin “ọjọ” iṣẹda kẹfa, ete rẹ̀ ti rin siwaju o si nrin siwaju si imuṣẹ oniṣẹgun rẹ̀. Nipa bayi, ko si idi fun irẹwẹsi fun awọn wọnni, gẹgẹ bi Jehofah Ọlọrun, funrarẹ̀, ti o ni igbagbọ ninu atubọtan iṣiṣẹ ete rẹ̀ ologo.

[Ibeere]

1. Ọlọrun ha sọ fun Adamu, nigba iṣẹda rẹ̀, pe o nilati di baba fun iran enia?

4. Bawo li Ọlọrun ṣe mu “oluranlọwọ” Adamu jade, kini on si pè e?

23, 24. (a) Kini fihan pe imuṣẹ ete Ọlọrun li opin “ọjọ keje” rẹ̀ ṣì mbẹ niwaju sibẹ? (b) Eṣe ti ko fi si idi fun irẹwẹsi lati ọdọ wa fun nini igbagbọ ninu imuṣẹ ete ologo Ọlọrun?