Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Dá Majẹmu kan fun Ijọba pẹlu Dafidi

A Dá Majẹmu kan fun Ijọba pẹlu Dafidi

Ori 10

A Dá Majẹmu kan fun Ijọba pẹlu Dafidi

1. Igba akọkọ wo li a sami si ninu 1 Awọn Ọba 6:1, esitiṣe ti idiwọn akoko yi fi ṣe dede?

ỌLỌRUN sami si awọn igba akoko tirẹ̀ funrarẹ̀ ni ibamu pẹlu ‘‘ete aiyeraiye’‘ Rẹ̀. Iru igba akoko kan bẹ li a sami si fun wa ninu iwe Awọn Ọba Kini, ọrinlenirinwo ọdun, lẹhin igbati awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, li ọdun kẹrin ijọba Solomoni lori Israeli, li oṣu Sifi ti iṣe oṣu keji, li o bẹrẹ si nkọ ile fun [Jehofah].’‘ Eyiyi jẹ idiwọn akoko ti o ṣe dede, nitoripe o jẹ lati igbati a dá awọn ọmọ Israeli ni ìdè kuro ni Egipti, kete lẹhinti nwọn bẹrẹsi ko ile ijọsin ninu aginju Sinai, si igbati Ọba Solomoni ọmọ Dafidi bẹrẹsi kọ́ tempili ni Jerusalemu. Eyiyi bẹrẹ lati Nisani 15, 1513 B.C.E., si 1034 B.C.E., Sifi (tabi, Iyyar) 1.—Numeri 33:1-4; 1 Awọn Ọba 6:37.

2, 3. (a) Eṣe ti awọn ọmọ Israeli fi rin kiri tobẹ ni aginju Sinai? (b) Bawo li o ti pẹ to ni ṣiṣẹgun Ilẹ Ileri na, lẹhinna bawo li a ṣe ṣakoso Wọn fun ọgọrọrun ọdun?

2 Sugbọn o, pupọ ti ṣẹlẹ ni awọn ọgọrun ọdun wọnni ti o fẹrẹ pe marun. Nitori ikuna lati ni igbagbọ ninu agbara Ọlọrun lati ṣẹgun awọn orilẹ-ede ti mbẹ ni Ilẹ Ileri nigbana, o di ọranyan fun awọn ọmọ Israeli lati rin kiri ni aginju Sinai fun eyiti o fẹrẹ to ogoji ọdun. Ni akoko na awọn agba Israeli ti o ti ṣọtẹ si kikọlu Ilẹ Ileri na labẹ idari Ọlọrun ni ọdun keji ijadelọ wọn li o ku sọnu. (Numeri 13:1 titi de 14:38) Li opin ogoji ọdun Ọlọrun lọna iyanu mu wọn rekọja odo Jordani kikun si Ilẹ Ileri na, ilẹ Kennani.

3 Lẹhinna, labẹ idari Joṣua, arọpo Mose, awọn ọdun ogun-jija fun ṣiṣẹgun ilẹ ọdun mẹfa li awọn ọmọ Israeli fi ṣiṣẹ gbigba ilẹ na ati lile awọn olugbe ilẹ na kuro. (Joṣua 14:1-10) Lẹhinna Ọlọrun fun awọn ọmọ Israeli ti o simi nisisiyi ni ila awọn onidajọ fun ọgọrọrun ọdun titi di igbati iyipada fi wa ninu ilana ijọba orilẹ-ede kan ni awọn ọjọ woli Samueli. Oluṣiro akoko kan ti o jẹ Ju ni ọgọrun ọdun mọkandinlogun sẹhin ni kukuru ṣe idiwọn akoko yi fun wa. Nigbati o nsọrọ ni ọjọ isimi kan ninu sinagogu na ni Antioku ti Pisidia, Asia Kekere, oluṣiro akoko yi wipe:

4, 5. (a) Igba akoko wo ni oluṣiro na ninu Bibeli sami si ninu itan Israeli ṣaju ki nwọn to ni awọn onidajọ? (b) Pẹlu awọn iṣẹlẹ wo ni igba akoko na bẹrẹ ti o si dopin?

4 ‘‘Ẹnyin enia Israeli, ati ẹnyin ti o bẹru Ọlọrun, ẹ fi eti silẹ. Ọlọrun awọn enia Israeli yi, yan awọn baba wa, o si gbe awọn enia na leke, nigbati nwọn ṣe atipo ni ilẹ Egipti, apa giga li o si fi mu wọn jade kuro ninu rẹ. Ni awọn igba ogoji ọdun li o fi mu súrù fun iwa wọn ni iju. Nigbati o si ti run orilẹ-ede meje ni ilẹ Kenaani, o si fi ilẹ wọn fun wọn ni ini fun iwọn adọta-le-ni-irinwo ọdun gbogbo eyini nigba nkan bi adọta-le-ni-irinwo ọdun, NW1. Ati lẹhin nkan wọnyi o fi onidajọ fun wọn, titi o fi di igba Samueli woli. Ati lẹhinna ni nwọn bere ọba: Ọlọrun si fun wọn ni Saulu ọmọ Kiṣi, ọkunrin kan ninu ẹya Benjamini, fun ogoji ọdun.’‘—Iṣe 13:14-21, English Revised Version Bible,ti a tẹjade ni England ni 1884 C.E. Wo Bibeli Douay Version pẹlu, ti a tẹjade ni 1610 C.E. Pẹlu-pẹlu, The Emphasised Bible, lati ọwọ J. B. Rotherham, ti a tẹjade ni 1897 C.E.

5 Pipin ilẹ fun Kalebu ati awọn ọmọ Israeli miran fun ogun-ini ṣẹlẹ ni ọdun 1467 B.C.E. Bi a ba ṣiro rẹ̀ ‘‘adọta-le-ni-irinwo ọdun’‘ yio mu wa pada si ọdun na 1918 B.C.E. Eyiyi li ọdun na ti a bi Isaaki, ọmọ Abrahamu nipasẹ Sarah, Ọlọrun si yan Isaaki dipo Iṣmaeli, agba ọmọkunrin Abrahamu lati ọdọ Hagari ẹrubirin. Sarah lati Egipti. Pẹlu ibura Ọlọrun tẹnumọ ọ fun Isaaki majẹmu ti On ba Abrahamu da fun jijogun ilẹ Kenaani, ati nisisiyi nihinyi li opin adọta-le-ni-irinwo ọdun Ọlọrun nṣe yiyan Ilẹ Ileri na fun awọn ọmọ Isaaki fun ijogun. Ninu iṣotitọ Jehofah Ọlọrun nrò timọtimọ mọ́: ‘‘ete aiyeraiye’‘ rẹ̀ fun bibukun fun gbogbo araiye.

6. (a) Bawo ni Gideoni Onidajọ ṣe fi iṣotitọ han si Ọlọrun gẹgẹbi, ọba alaṣẹ? (b) Bawo ni Abimeleki ọmọ Gideoni ṣe huwa bi ọba?

6 Nigba akoko onidajọ mẹdogun lati Joṣua si Samueli, awọn enia Israeli gbiyanju lati rò. Gideoni, ọmọ Joaṣi ti ẹya Manasseh, onidajọ kẹfa, lati gbe ila idile awọn ọba alakoso kalẹ ninu idile rẹ̀, dipo nini Jehofah Ọlọrun gẹgẹ bi Ọba. Ṣugbọn Gideoni jẹ olotọ si Ọba Alakoso Israeli o si kò ifilọni fun iṣakoso silẹ, ni wiwipe: ‘‘Emi ki yio ṣe olori nyin, bẹni ọmọ mi ki yio ṣe olori nyin: [Jehofah] ni yio má ṣe alaṣẹ nyin.’‘ (Awọn Onidajọ 8:22, 23) Ọkan ninu awọn ọpọ ọmọ Gideoni, ti a npe ni Abimeleki (ti o tumọsi ‘‘Ọba Ni Baba Mi’‘), lo agbara lori awọn ti o ni ilẹ Ṣekemu lati fi i joye lori wọn. O bọ́ si abẹ awọn idajọ Ọlọrun mimuna, lẹhinti o si ti jọba fun ọdun mẹta, obirin kan li o ṣe iku pa a ninu ogun.—Awọn Onidajọ 9:1-57.

ỌBA KAN LORI GBOGBO ISRAELI

7. Nigbawo ati bawo ni Israeli ṣe di ẹniti o ni ọba enia ti Ọlọrun yan, bawo li o si ti jọba pẹ to?

7 Ni ọjọ ogbó onidajọ kẹdogun, Samueli woli, awọn agbagba Israeli tò ọ wá pẹlu ẹ̀bẹ̀ na pe: ‘‘Njẹ fi ẹnikan jẹ ọba fun wa, ki ó le má ṣe idajọ wa, bi ti gbogbo orilẹ-ede.’‘ Samueli kà eyi si gẹgẹ bi kikọ on silẹ gẹgẹ bi onidajọ ti Ọlọrun yan, ṣugbọn Jehofah wi fun u pe: ‘‘Gbé ohun awọn enia na ni gbogbo eyiti nwọn sọ fun ọ: nitoripe iwọ kí nwọn kọ̀, ṣugbọn emi ni nwọn kọ̀ lati jẹ ọba lori wọn.’‘ Ọlọrun sọ fun Samueli lati kilọ fun awọn ọmọ Israeli nipa gbogbo iṣoro ti yio tumọsi fun wọn lati ní ọba kan ti a le fojuri, sibẹ nwọn fihan pe nwọn nfẹ iru ọba bẹ. Ọlọrun, gẹgẹ bi Oluwa ọba alaṣẹ lori Israeli, ṣe yiyan ọkunrin na lati jẹ enia ọba ekini fun Israeli. O rán Samueli lati fi ororo yan Saulu ọmọ Kiṣi ti ẹya Benjamini lati jẹ ọba. Li ọdun na 1117 B.C.E. a fi Saulu joye gẹgẹ bi ọba ni ilu Mispa. ‘‘Gbogbo enia si hó yé, nwọn si wipe, Ki Ọba ki o pẹ!’‘ Saulu si jọba fun ogoji ọdun.—1 Samueli 8:1 titi de 10:25; Iṣe 13:21. *

8. (a) Ni ọdun kọkanla iṣakoso Saulu, ibimọ wo li o ṣẹlẹ ni Betlehemu? (b) Kini Mika sọtẹlẹ nipa Betlehemu?

8 Li ọdun kọkanla ijọba Saulu ohun ti o dabi ainilári kan ṣẹlẹ ni ilu Betlehemu ni agbegbe ẹya Juda. Jesse ara Betlehemu bi ọmọ kẹjọ, ẹniti on pe ni Dafidi. Saulu Ọba tabi ẹnikẹni miran ni Israeli ko mọ̀ rara pe ọmọ kekere ti a ṣẹṣẹ bi yi yio di olokiki tobẹ ti ibiti a gbe bi i, Betlehemu, yio di ibiti ao ma pe ni ‘‘ilu Dafidi’‘ li ọjọ kan. Ko si ẹnikẹni ti o mọ̀ nigbana pe, nkan bi ọdunrun ọdun lẹhinna, ao sọ asọtẹlẹ nipa ilu Dafidi pe: ‘‘Ṣugbọn iwọ, Betlehemu Efrata, bi iwọ ti jẹ kekere lárin awọn ẹgbẹgbẹrun Juda, ninu rẹ ni ẹniti yio jẹ olori ni Israeli yio ti jade tẹ mi wá; ijadelọ rẹ̀ si jẹ lati igbánì, lati aiyeraiye.’‘ (Mika 5:1, Leeser; JPS; 5:2, NEB; NW) Àsọtẹlẹ yi li awọn aṣaju isin Ju ni ọgọrun ọdun ekini ṣáju Sanmani Tiwa loye pe o nsọ nipa Messiah. Nitorina a nilati bi ‘‘iru-ọmọ obirin’‘ Ọlọrun na ni Betlehemu.

9. Loju iwa ailoye Saulu, kini Ọlọrun mu ki Samueli sọ fun Saulu nipa ijọba na, tani Ọlọrun yio si yan si itẹ na?

9 Biotiwukiori, ṣáju eyi, lẹhinti Ọba Saulu ti jọba fun ọdun meji, o juwọsilẹ fun ainigbagbọ o si huwa igberaga, ailọgbọn-ninu, ninu ipo. ‘‘Samueli si wi fun Saulu pe, Iwọ ko hu iwa ọlọgbọn: iwọ ko pa ofin [Jehofah] Ọlọrun rẹ mọ, ti on ti pa li aṣẹ fun ọ: nitori nisisiyi ni [Jehofah] iba fi idi ijọba rẹ mulẹ lori Israeli lailai. Ṣugbọn nisisiyi ijọba rẹ ki yio duro pẹ: [Jehofah] ti wá fun ara rẹ̀ ọkunrin ti o wù u li ọkàn rẹ̀: [Jehofah] paṣẹ fun u ki o ṣe olori fun awọn enia rẹ̀, nitoripe iwọ ko pa aṣẹ ti [Jehofah] fi fun ọ mọ.’‘ (1 Samueli 13:1-14) ‘‘Ọkunrin na ti o wú ọkàn [Ọlọrun]’‘ li a koiti bíi sibẹ, nitoripe a sọ awọn ọrọ wọnni ni awọn ọpọ ọdun ṣaju bibi Dafidi ni Betlehemu. Eyiyi mu u ṣe kedere pe Ọlọrun Ọga Ogo Julọ yio lo agbara ati ẹtọ rẹ̀ ki o si ṣe yiyàn funrarẹ̀ ọmọ Israeli kan ti yio rọpo Ọba Saulu. Ni ṣiṣe bẹ yio rọ̀ mọ́: ‘‘ete aiyeraiye’‘ rẹ̀ niti Messiah na.

10, 11. (a) Bawo li a ṣe yan Dafidi lati jẹ ọba lọjọ iwaju fun Israeli? (b) Bawo ni Dafidi ṣe ko agbako owú jijẹ ti apania lati ọdọ Saulu, nibo li on si ti kọkọ di ọba?

10 Nigbati Dafidi ṣi jẹ ọmọkunrin oluṣọ-agutan ti koiti pe ogún ọdun ni Betlehemu, Ọlọrun yàn a gẹgẹ bi ọkunrin ti o wù ọkàn rẹ̀. Biotilẹjẹpe Dafidi ki iṣe akọbi ọmọ Jesse ṣugbọn ti o wulẹ jẹ ọmọkunrin kẹjọ, Ọlọrun rán Samueli lọ si Betlehemu lati fi ororo yan Dafidi lati di ọba Israeli li ọjọ iwaju.

11 Dafidi bọ́ si ojutaiye nigbati o jẹ pe on nikanṣoṣo ninu gbogbo awọn ọmọ Israeli ti o yọda ara rẹ̀ lati dojukọ Goliati òmìrán Filistini ti o gbe ipenija dide ni pápá ogun ti o si pa a pẹlu kànnà-kànnà ti o ta si agbari Goliati. (1 Samueli 16:1 titi de 17:58) A mu Dafidi lọ si ẹgbẹ ọmọ ogun Ọba Saulu, okiki rẹ̀ pẹlu awọn enia na si ga soke rekọja ti ọba. Eyiyi mu ki Saulu jowu gan o si gbiyanju lati pa- Dafidi ki o si tipa bayi dí i lọwọ ki o maṣe ṣe idina fun gbigbe ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀ funrarẹ̀ kà ori itẹ Israeli. Laipẹ ọgbẹ́ ti o mu iku dani ninu ogun, pẹlu ṣiṣubu rẹ̀ sori idà on tikararẹ̀ lati mu ki iku rẹ̀ yá kánkán, fi opin si jijẹ-ọba Saulu. Iṣboṣeti, ọmọ Saulu ti o ṣẹhin dè e, li a fi jẹ ọba nipasẹ awọn wọnni ti o rò mọ ila idile Saulu, ṣugbọn kiki lori ẹya mọkanla Israeli pere ni. Awọn enia Juda fi ororo yan ọba Dafidi lori wọn ni Hebroni ni agbegbe Juda. Eyini jẹ li ọdun 1077 B.C.E.—2 Samueli 2:1-11; Iṣe 13:21, 22.

12. Nigbawo ati bawo li a ṣe sọ Dafidi di ọba lori gbogbo Israeli, ibere wo li o si dide nisisiyi niti ‘‘ọpa alade’‘ ati ti ‘‘alaṣẹ’‘?

12 Iṣboṣeti ọmọ Saulu wà lori itẹ Israeli boya fun ọdun meje ati oṣu mẹfa lẹhinna ni awọn ọmọ abẹ ijọba rẹ̀ pa a. (2 Samueli 2:11 titi de 4:8) Gbogbo ẹya na jẹ̀wọ Dafidi nisisiyi gẹgẹ bi ẹniti Jehofah yan nwọn si fi ororo yan Dafidi gẹgẹ bi ọba lori gbogbo Israeli, ni Hebroni. Eyiyi ṣẹlẹ li ọdun 1070 B.C.E. (2 Samueli 4:9 titi de 5:5) Nipa bayi, ni ibamu pẹlu asọtẹlẹ Jakobu lori akete iku gẹgẹ bi a ti ṣe kọ ọ silẹ ninu Genesisi 49:10, ‘‘ọpa alade!’‘ ati ‘‘olofin’‘ ti wá lati ẹya Juda. Lori ipilẹ wo, nisisiyi, ni awọn ami ọba wọnni ‘‘ki yio ti ọwọ Juda kuro . . . titi Ṣiloh yio fi de’‘?

13. Bawo ni Dafidi ṣe jẹ ‘‘ẹni ami ororo’‘ nitotọ, tani on si nṣe apẹrẹ rẹ̀?

13 Nitori ifororoyan lẹmẹta fun jijẹ ọba, dajudaju a le pe Ọba Dafidi ni ‘‘ẹni ami ororo’‘ tabi ‘‘messiah’‘ (Heberu: ma-shi’ahh), bi o ti wà ninu 2 Samueli 19:21; 22:51; 23:1. Ni kedere, a lo Dafidi gẹgẹ bi apẹrẹ asọtẹlẹ fun Messiah olokiki, ‘‘iru-ọmọ obirin’‘ Ọlọrun li ọrun. (Wo Esekieli 34:23.) Niti tôtọ, Ọlọrun ri i pe o dara lati yan Dafidi lati wà ni ila idile eyiti o mu Messiah jade ninu ‘‘ete aiyeraiye’‘ Ọlọrun. Bawo li eyi ṣe ṣẹlẹ?

14. Ilu wo ni Dafidi fi ṣe olu ilu gbogbo Israeli, ohun mimọ wo li on si gbekalẹ nibẹ?

14 Kete lẹhin fifi ororo yan a bi ọba lori Israeli ti a sopọ ṣọkan ni 1070 B.C.E., Dafidi ṣẹgun ilu awọn ara Jebusi ti a npe ni Jebusi o si pe orukọ rẹ̀ ni Jerusalemu. Nibẹ li o gbe ijọba rẹ̀ lọ o si sọ ilu giga yi di olu ilu rẹ̀, nitoripe o wà li agbedemeji ju Hebroni lọ, nitoripe o wà lẹba álà lárin awọn agbegbe Juda ati Benjamini. (Awọn Onidajọ 1:21; 2 Samueli 5:6-10; 1 Kronika 11:4-9) Ko pẹ lẹhin eyini, Ọba Dafidi gba ti apoti majẹmu mimọ ti Jehofah rò. F’un ọpọ ọdun a ti gbà a laye lati di ohun ti a gbe kuro ninu Ibi Mimọ Julọ ninu agọ ajọ ni Ṣiloh ni agbegbe Efraimu. (1 Samueli 1:24; 4:3-18; 6:1 titi de 7:2) Dafidi rò pe o yẹ ki apoti majẹmu na wà ni olu ilu. Nitorina o mu ki a gbé e wá ki o si wà ninu agọ kan lẹba afin rẹ̀.—2 Samueli 6:1-19.

15. Majẹmu wo ni Jehofah ba Dafidi dá nisisiyi, lati inu imọriri fun ohun wo ti Dafidi ṣe?

15 Sugbọn, Dafidi ni imọlara idẹrubani, nitoripe, on ọba enia kan lasan, ngbe ni áfin ọba nigbati apoti majẹmu Jehofah, Ọlọrun otitọ na ati Ọba Israeli nitotọ, ngbe ni agọ kekere kan lasan. Lati fi awọn ọran si ibiti o yẹ wọn, Dafidi gbérò kíkọ ile kan ti o yẹ, tempili kan, fun Ọlọrun Ọga Ogo Julọ ati Ọba Alaṣẹ Agbaiye. Ṣugbọn Jehofah ko tẹwogba a fun Dafidi lati kẹ iru tempili kan bẹ. Nipasẹ Natani woli Rẹ̀ o sọ fun Dafidi pe yio jẹ anfani fun ọmọ rẹ̀ kan ti o fẹran alafia lati kọ́ tempili na ni Jerusalemu. Nigbana, ni imọriri fun ifọkansin Dafidi fun ijọsin mimọ Ọlọrun, Jehofah ṣe ohun iyanu kan’ pẹlu ọkunrin yi ẹniti o ‘‘wù ọkan rẹ̀.’‘ F’unrarẹ̀, li o gbe majẹmu kan kalẹ pẹlu Dafidi fun ijọba ainipẹkun kan. O wipe:

“[Jehofah] si wi fun ọ pe, ‘‘[Jehofah] yio kọ ile kan fun ọ. Nigbati ọjọ rẹ ba pé, ti iwọ o si sùn pẹlu awọn baba rẹ, emi o si gbe iru-ọmọ rẹ leke lẹhin rẹ, eyiti o ti inu rẹ jade wa, emi o si fi idi ijọba rẹ̀ kalẹ. On o si kọ ile fun orukọ mi, emi o si fi idi itẹ ijọba rẹ̀ kalẹ lailai. Emi o má ṣe baba fun u, on o si má; jẹ ọmọ mi, Bi on ba dẹṣẹ, emi o si fi ọpa enia ati ìnà awọn ọmọ enia nà a. Ṣugbọn ánu mi ki yio yipada kuro lọdọ rẹ̀, gẹgẹ bi emi ti mu u kuro lọdọ Saulu, ti emi ti mu u kuro niwaju rẹ, A o si fi idile rẹ ati ijọba rẹ mulẹ niwaju rẹ titi lai: a o si fi idi itẹ rẹ mulẹ titi lai.”—2 Samueli 7:1-16; 1 Kronika 17:1-15.

16. Adura ọpẹ wo ni Dafidi gbà si Jehofah fun eyi?

16 Dafidi’ gba adura ọpẹ o si pari rẹ̀, nipa wiwipe:

“Njẹ, [Jehofah] Ọlọrun, iwọ li Ọlọrun na, ọrọ rẹ wọnni si jasi otitọ, iwọ si jẹjẹ nkan rere yi fun iranṣẹ rẹ. Njẹ, jẹ ki o wù ọ lati bukun idile iranṣẹ rẹ, ki o wà titi lai niwaju rẹ: nitori iwọ, [Jehofah] Ọlọrun, li o ti sọ ọ: si jẹ ki ibukun ki o wà ni idile iranṣẹ rẹ titi lai, nipasẹ ibukun rẹ.”—2 Samueli 7:18-29; 1 Kronika 17:16-27.

17. Niha ọdọ Ọlọrun, kini ohun ti a fi tì majẹmu yi lẹhin?

17 Ileri majẹmu na fun Dafidi ni ibura Ọlọrun tì lẹhin:

“[Jehofah] ti bura nitotọ fun Dafidi, (On ki yio yipada kuro ninu rẹ̀) Ninu iru-ọmọ rẹ li emi o gbe kalẹ si ori itẹ rẹ. Bi awọn ọmọ rẹ yio ba pa majẹmu mi mọ ati ẹri mi ti emi o kọ wọn, awọn ọmọ wọn pẹlu yio joko lori itẹ rẹ lailai.’‘—Orin Dafidi 132:11, 12.

‘‘Anu mi li emi o pamọ fun u lailai, ati majẹmu mi yio si ba a duro ṣinṣin. Iru-ọmọ rẹ pẹlu li emi o mú pẹ titi, ati itẹ rẹ bi ọjọ ọrun . . . Majẹmu mi li emi ki yio dà, Bẹli emi ki yio yí ohun ti o ti ẹ̀tò mi jade pada. Lẹrinkan ni mo ti fi iwa mimọ mi bura pe, Emi ki yio purọ fun Dafidi. Iru-ọmọ rẹ yio duro titi lailai, ati itẹ rẹ bi ọrun niwaju mi.”—Orin Dafidi 89:28-36. Tun wo Jeremiah 33:20, 21 pẹlu.

18. Asọtẹlẹ Isaiah kede pe ijọba Dafidi yio pese ipilẹ fun ijọba titobiju wo?

18 Gẹgẹ bi majẹmu na pẹlu Ọba Dafidi ti wi, ijọba rẹ̀ nilati pese ipilẹ fun ijọba Messiah Titobiju ti mbọ. Idi ni yi ti woli Isaiah, ni ọgọrọrun ọdun lẹhinna, ṣe di ẹniti a misi lati sọtẹlẹ: ‘‘Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yio si wà li ejika rẹ̀: a o si ma pe orukọ rẹ̀ ni Iyanu, Oludamọran, Ọlọrun Alagbara, Baba Aiyeraiye, Ọmọ-Alade Alafia. Ijọba yio bí si i, alafia ki yio ni ipẹkun, lori itẹ Dafidi, ati lori ijọba rẹ̀, lati má tọ ọ, ati lati fi idi rẹ̀ mulẹ, nipa ẹtọ ati ododo lati isisiyi lọ, ani titi lai. Itara Ẹni Aiyeraiye awọn ọmọ ogun ni yio ṣe eyi.’‘—Isaiah 9:5, 6, gẹgẹ bi itumọ ọmọwe Heberu na Rabbi Leopold Pheinkard Zunz, German, itẹjade ikẹrindinlogun ti 1913 C.E. ti wi. Tun wo Isaiah 9:6, 7, AV; RS; NEB; Jerusalem Bible.

19. Gẹgẹ bi asọtẹlẹ Mika ti wi ‘‘ọmọ’‘ yi li a nilati bi ni ilu wo, eyiyi si jẹ ami ifinihan fun tani?

19 Gẹgẹ bi asọtẹlẹ Mika 5:1 (Zunz; 5:2, AV; NW) ti wi, ọmọ Messiah yi li a o bí, ọmọ ọba yi li ao fifunni ni Betlehemu ti Efrata ni agbegbe Juda. Ibiti a bi enia si yi nilati jẹ ọkan ninu awọn ami ifinihan fun Messiah totọ na, ‘‘iru-ọmọ’‘ iṣapẹrẹ ‘‘obirin’‘ Ọlọrun. Betlehemu, ki si iṣe Jerusalemu ilu ọba, ni ibiti a bi Ọba Dafidi, babanla si, nitorina li a si ṣe npe e ni ilu Dafidi.

ILA IDILE AWỌN ỌBA TI DAFIDI

20. Bawo ni ila idile ọba Dafidi ti pẹ to lori itẹ, fun ọdun melo si li awọn ọmọ Israeli fi ni ọba?

20 Niti imuṣẹ fun majẹmu ijọba yi fun Dafidi, ila awọn ọba kan ni Jerusalemu bẹrẹ, gbogbo wọn ninu ila idile Ọba Dafidi. Bi a ba kà a lati igbati Dafidi jọba ni Jerusalemu ni 1040 B.C.E. ila idile ọba yi ti o jẹ ti awọn ọba Dafidi ni Jerusalemu wà fun 463 ọdun, tabi titi di 607 B.C.E. Nitorina eyi tumọsi pe, nigbati a ba kà a lati ọdun na 1117 B.C.E., nigbati woli na Samueli fi ororo yan Saulu gẹgẹ bi ọba lori gbogbo Israeli, orilẹ-ede Israeli ní awọn ọba ti a le fojuri fun 510 ọdun. Ṣugbọn, Jehofah li ọba ti a ko fojuri.

21. Dafidi ha goke lọ si ọrun nigba iku bi, tani Dafidi si sọtẹlẹ pe ao kesi lati joko li ọwọ ọtun Ọlọrun?

21 Gẹgẹ bi ọba aṣoju Ọlọrun ẹniti o yàn a ti o si sọ ọ di ẹni ami ororo lati jẹ ọba lori Israeli, Ọba Dafidi joko lori ‘‘itẹ Jehofah’‘ ni Jerusalemu. (1 Kronika 29: 23) Ṣugbọn on ko joko li ọwọ ’ọtun Jehofah, nitoripe itẹ Jehofah mbẹ li ọrun. (Isaiah 66:1) Nigbati o ku ni 1037 B.C.E. Dafidi ko goke lọ si awọn ọrun ti ẹmi ki o si joko li ọwọ ọtun Jehofah nibẹ. A ko kesi i lati ṣe bẹ; ṣugbọn titi de ọgọrun ọdun ekini Sanmani Igba Tiwa awọn ọmọ Israeli le mọ ki nwọn si ri ibiti a sin Dafidi si. Kaka bẹ, Dafidi funrarẹ̀ li a misi nipasẹ Ọlọrun lati sọ asọtẹlẹ, ninu Orin Dafidi 110:1-4, pe Messiah ti o wà lẹhin on ẹniti yio dabi Melkisedeki Ọba-Alufa li ẹni na ti Jehofah yio kesi lati joko li ọwọ ọtun Rẹ̀ li ọrun.

22. Bawo ni Solomoni ati eyiti o pọ julọ ninu awọn arọpo rẹ̀ lori itẹ ṣe huwa, lati igbawo si ni Jerusalemu ko ti ni ila idile Dafidi lori itẹ?

22 Solomoni, ọmọ kekere Dafidi, tẹle e lori itẹ Jerusalemu, ‘‘itẹ Jehofah.’‘ Gẹgẹ bi ileri atọrunwa na ti wi, on li a ṣe ojurere si fun kikọ tempili na lori Oke Moriah ni Jerusalemu, ti o si pari rẹ̀ li ọdun 1027 B.C.E. (1 Awọn Ọba 6:1-38) Nigbati Solomoni ndarugbo o di alaiṣótọ si Ọlọrun ẹniti on ti kẹ tempili fun. Eyiti o pọ julọ ninu awọn arọpo rẹ̀ lori itẹ Jerusalemu li o yipada si buburu pẹlu. Eyiti o kẹhin ninu awọn ọba ila Dafidi wọnyi lati joko lori itẹ Jerusalemu ni Sedekiah. Fun iṣọtẹ rẹ̀ lodi si ọba Babiloni, ẹniti o ti sọ Sedekiah di ẹka ọba, a kô o lọ li ẹrú si Babiloni, pẹlu fifi ilu Jerusalemu silẹ sẹhin ati tempili ẹlẹwa ninu iparun. (2 Awọn Ọba 24:17 titi de 25:21) Lati igba ọdun onijamba na 607 B.C.E. koiti si ọba lati ila idile Dafidi ti o joko lori itẹ Jerusalemu.

23. Majẹmu ijọba na ha ti kuna tabi a ha ti fagile e, idaniloju wo ni Ọlọrun si fifunni nipasẹ Esekieli nipa eyi?

23 Eiyini ha fihan pe majẹmu ijọba pẹlu Dafidi ti kuna tabi a ti fagile e? Bẹkọ rara! Ọlọrun pese idaniloju lodi si eyini. Ni nkan bi ọdun kẹrin ṣaju irẹsilẹ Sedekiah kuro lori itẹ ati ikolẹru rẹ̀ lọ si Babiloni, Ọlọrun misi woli rẹ̀ Esekieli lati sọ nipa ọba ti o kẹhin lori itẹ Jerusalemu yi pe:

“Ati iwọ, alailọwọ̀ ẹni-buburu, ọmọ alade Israeli, ẹniti ọjọ rẹ̀ de, nigba aiṣedede ikẹhin. Bayi li [Jehofah] Ọlọrun wi, ‘Mú fila ọba kuro, si ṣí ade kuro, eyi ko ni jẹ ọkanna: gbe ẹniti o rẹlẹ ga, si rẹ̀ ẹniti o ga silẹ. Emi o bì i ṣubu, emi o bì i ṣubu, emi o bì i ṣubu; ki yio si sí mọ, titi igbati ẹniti o ni i ba de; emi o si fi fun u.’”—Esekieli 21:25-27.

24. Kini a nilati rẹ̀ silẹ, nigbawo si ni odikeji eyi yio ṣẹlẹ, bawo sì ni?

24 Awa ha ri oye eyini bi? Jehofah funrarẹ̀ yio ṣe iparun ijọba ila idile Dafidi ni Jerusalemu. Awọn nkan ko ni ri bi nwọn ti nri tẹlẹ. Awọn agbara Keferi ti o ti rẹlẹ niwaju Ọlọrun li ao gbega, ijọba awọn enia ti Jehofah yàn lori ilẹ aiye li ao rẹ̀ silẹ, labẹ awọn agbara aiye Keferi. Akoko ijẹ gaba aiye lati ọwọ awọn Keferi laisi idilọwọ lati ọwọ ijọba Ọlọrun gidi kan ni Jerusalemu yio ma ba a lọ titi ẹni na ti ‘‘o ni i’‘ yio fi de, eyini ni, Messiah totọ na, ti a ṣeleri, Oluwa Jehofah Ọba Alaṣẹ yio si fi ijọba na fun u. Nigbana awọn agbara aiye Keferi kò tun ni wà loke lati jẹgaba lori aiye. Ijọba Messiah yio gba iṣakoso agbaiye. Nipa bayi, gẹgẹ bi majẹmu ti a ba Dafidi dá ti wi, ijọba rẹ̀ yio jẹ ijọba ainipẹkun. Itẹ rẹ̀ nilati wà titi lai;

25. Laibikita fun isọdahoro Jerusalemu ni 607 B.C.E., awọn majẹmu ati ete wo li o ṣì duro?

25 Nitorina, biotilẹjẹpe titi di oni oloni yi a koiti tun gbe itẹ Dafidi kalẹ ni Jerusalemu ni Agbedemeji Ila Orùn, gbogbo rẹ̀ ko pari fun awọn wọnni ti o ní ireti si Messiah na, ‘‘iru-ọmọ obirin’‘ Ọlọrun li ọrun. Nitotọ, nigba ikore 607 B.C.E. ilu itẹ Jerusalemu ati tempili rẹ̀ li a parun. Ilu Betlehemu ti o wà nitosi, ilu Dafidi, li a parun lati ọwọ awọn aṣẹgun ara Babiloni. Sibẹ, majẹmu Ofin ti a dá pẹlu Israeli lori Oke Sinai ni Arabia mba iṣẹ lọ. Pẹlupẹlu, majẹmu fun ijọba ainipẹkun ti a dá pẹlu Dafidi mba iṣẹ lọ. ‘‘Ete aiyeraiye’‘ Ọlọrun niti Messiah rẹ̀ duro. Majẹmu ijọba Ọlọrun ko ni kuna. Bẹ si ni ete rẹ̀!

[ALAYE ISALE IWE]

^ ìpínrọ̀ 7 Ninu Antiquities of the Jews, Iwe 10, ori 8, ẹsẹ 4, Flavius Josephus ti ọgọrun ọdun kini Sanmani Tiwa yi yan ogún ọdun fun Ọba Saul. Ṣugbọn ninu Iwe 6, ori 14, ẹsẹ 9, Josephus kọwe pe: “Nisisiyi Saulu, jọba fun ọdun mejidinlogun nigbati Samueli ṣì wà layé, ati lẹhin iku rẹ̀ meji,” eyiti awọn iwe afọwọkọ eyiti Josephus ṣe fi eyi kún u: “ati ogún”; ti o sọ apapọ gbogbo rẹ̀ di ogoji ọdun.

[Ibeere]