Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Fi Awọn Ohun Ijinlẹ Miran Nipa Messiah na Hàn

A Fi Awọn Ohun Ijinlẹ Miran Nipa Messiah na Hàn

Ori 13

A Fi Awọn Ohun Ijinlẹ Miran Nipa Messiah na Hàn

1, 2. (a) Bawo li a ti ṣe tumọ ọrọ na “ohun ijinlẹ”? (b) Ete wo niti Kristi li Ọlọrun ti sọ di ohun ijinlẹ ti a ṣipaya fun wa?

OHUN ijinlẹ li a ti tumọ gẹgẹ bi “otitọ eyikeyi ti ko ṣe mọ bikoṣe nipasẹ ifihan Ọlọrun.” O jẹ “ohun ijinlẹ” kan ti Ọlọrun fihan li akoko rẹ̀. (Romu 16:25, 26) Fun akoko gigun o jẹ ohun ijinlẹ kan tabi aṣiri mimọ kan nipa ẹniti yio jẹ Messiah na, tabi “iru-ọmọ” “Obirin” Ọlọrun li ọrun. Pẹlupẹlu, ete Ọlọrun niti Messiah na tabi Kristi jẹ ohun ijinlẹ tabi aṣiri mimọ kan fun igba gigun kan. Ṣugbọn ninu akoko rẹ̀ ti o yan Ọlọrun fihan, tabi ko tun sọ ọ di ohun ikọkọ mọ, pe o jẹ ete rẹ̀ lati lo Messiah na tabi Kristi niti iṣakoso gbogbo nkan, gẹgẹ bi niti ṣiṣakoso ile kan nipasẹ ọmọ Ọdọ kan. Iru iṣakoso bẹ fun iṣọkan yio tumọsi pe Ọlọrun yio fi ori gbogbo nkan si ọwọ Messiah (Kristi) na tabi kò gbogbo nkan jọ pọ lẹkan si i labẹ Messiah tabi Kristi gẹgẹ bi ori. O jẹ inurere fun Ọlọrun gẹgẹ bi Alakoso kan lati fi eyi han, gan gẹgẹ bi a ti ka a:

2 “Eyiti o sọ di pupọ fun wa ninu gbogbo ọgbọn ati oye, ẹniti o ti sọ ohun ijinlẹ ifẹ rẹ̀ di mimọ̀ fun wa, gẹgẹ bi idunnu rẹ̀, eyiti o ti pinnu ninu rẹ̀, fun iṣẹ iriju [abojuto nipasẹ ọmọ ọdọ kan] ti kikun akoko na, ki o le ko ohun gbogbo jọ ninu Kristi [Ma-shi’ahh], iba ṣe eyiti mbẹ ninu awọn ọrun, tabi eyiti mbẹ li aiye, ani ninu rẹ̀. Ninu ẹniti a fi wa [awọn ọmọ-ẹhin Kristi] ṣe ini rẹ̀ pẹlu, awa ti a yan tẹlẹ, gẹgẹ bi ipinnu [Griki: pro’thesis] ẹniti nṣiṣẹ ohun gbogbo gẹgẹ bi ìmọ ifẹ rẹ̀. Ki awa ki o le jẹ fun iyin ogo rẹ̀, awa ti a ti ni ireti ṣaju ninu Kristi.”—Efesu 1:8-12.

3. Kini ileri Ọlọrun fun “majẹmu titun” kan tumọsi fun majẹmu Ofin lailai ti Mose ati ete rẹ̀?

3 O wà ni ibamu pẹlu ete Ọlọrun yi pe ki Messiah na bẹrẹsi fi ipilẹ lelẹ fun ijọ kan eyiti on yio jẹ ori rẹ̀ nipasẹ yiyan atọrunwa. Awọn memba kọkan ninu ijọ yi labẹ Kristi li a ko yan tẹlẹ tabi pinnu li ẹnikọkan ; afi kiki iye awọn memba ati awọn iwa Kristian wọn li a ti pinnu tẹlẹ. Gan gẹgẹ bi o ti fihan nipa awọn ẹkọ rẹ̀, Jesu mọ pe asọtẹlẹ Jeremiah 31:31-34 sọtẹlẹ bi Jehofah Ọlọrun yio ṣe dá “majẹmu titun” kan pẹlu awọn enia Rẹ̀. Bẹ gẹgẹ, majẹmu Ofin lailai eyiti Mose ti jẹ alarina rẹ̀ fun awọn Ju nipa ti ara yio wá si opin. Gẹgẹ bi a ti sọ ọ ninu Heberu 8:13: “Li eyiti o wipe, Majẹmu titun, o ti sọ ti iṣaju di ti lailai, ṣugbọn eyi ti o ndi ti lailai ti o si ngbó, o mura ati di asan.” Nigba akoko iṣẹ Jesu ni gbangba majẹmu Ofin Mose na ti ju 1,540 ọdun li ọjọ ori. Sibẹ lẹhin gbogbo akoko nì o ti kuna lati mu “ijọba alufa ati orilẹ-ede mimọ” jade. (Eksodu 19:6) Ani titi di oni, ọgọrun ọdun lọna mọkandinlogun lẹhinna, awọn Ju nipa ti ara wọnni ti nwọn sọ wipe nwọn ṣi wà labẹ majẹmu Ofin Mose sibẹ kuna lati pese fun Ọlọrun “ijọba alufa ati orilẹ-ede mimọ” kan, ani oye alufa Aaroni wọn pápa ti foriṣanpọn lati 70 C.E.

4. Kini a nilati wi nipa ipilẹ ijọ Kristian, nigbawo li a si kọkọ gbe e kalẹ?

4 Jesu fi sọkan pe orilẹ-ede Israeli li a gbeka ori awọn baba-nla mejila, awọn ọmọ Jakobu mejila. (Genesisi 49:28) Nitorina, lara awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Jesu yan awọn ọkunrin mejila awọn ẹniti on pe ni “aposteli” (awọn ti a ran jade) awọn ẹniti yio si jẹ ipilẹ onipokeji le e lori ẹniti o jẹ ipilẹ ijọ na. (Marku 3:14; Luku 6:13; Efesu 2:20) Ni titọka si ara rẹ̀ gẹgẹ bi apata ipilẹ, o wi li etigbọ awọn aposteli mejila na pe: “Ori apata yi li emi yio kọ ijọ mi le; ẹnu ọna ipo-oku ki yio si le bori rẹ̀.” (Matteu 16:18) Ṣugbọn, titi di akoko iku rẹ̀ Jesu ṣi mọ sibẹ orilẹ-ede Israeli gẹgẹ bi ijọ Ọlọrun, ti o nwasu ninu awọn sinagogu rẹ̀ ti o si nkọni ninu tempili rẹ̀ ni Jerusalemu. O jẹ igba ekini ni adọta ọjọ lati igba ọjọ ajinde rẹ̀ kuro ninu oku ni a dá ijọ na silẹ eyiti on jẹ ori ati ipilẹ rẹ̀. Lori ipilẹ wo li a le gba sọ eyini? Lori ipilẹ alagbara ti o tẹle e yi:

5. Kini a tú jade li ọjọ ajọdun awọn Ọsẹ, sori tani, ki si ni alaye Peteru nipa bi a ti ṣe tú u jade?

5 Li ọjọ ajọdun Shavuoth, tabi Pentikosti ati ni imuṣẹ asọtẹlẹ Joeli 2:28, 29, a tú ẹmi mimọ Ọlọrun jade. Sori tani? Ihaṣe sori orilẹ-ede Israeli ti nṣe ajọyọ ajọdun awọn Ọsẹ (Shavuoth) rẹ̀ nibẹ ni Jerusalemu? Bẹkọ; ṣugbọn sori nkan bi ọgọfa awọn olotọ ọmọ-ẹhin Jesu Kristi, ti o pejọpọ ninu yara oke kan ni Jerusalemu. Ni ẹri ti o ṣé fojuri ti o si ṣé gbọ nipa eyi, “ẹ̀là ahọn bi ti ina” si ràbàbà le olukuluku wọn lori wọn si bẹrẹsi fi ede fọ yatọ si ede ibilẹ wọn. Fun ẹgbẹgbẹrun awọn Ju ti o pejọpọ ti o yalẹnu, aposteli Peteru ṣalaye imuṣẹ asọtẹlẹ Joeli 2:28, 29 nipa itujade ẹmi Ọlọrun li o nṣẹlẹ, lẹhinna li o fikun u pe:

“Jesu na yi li Ọlọrun ti ji dide, ẹlẹri eyiti gbogbo wa ise. Nitorina bi a ti fi ọwọ ọtun Ọlọrun gbe e ga, ti o si ti gba ileri ẹmi mimọ lati ọdọ Baba, o tu:eyi silẹ, ti ẹnyin ri, ti ẹ si gbọ. Dafidi ko sa goke lọ si ọrun: ṣugbọn on tikararẹ̀ wipe, [Jehofah] wi fun Oluwa mi pe, Joko li ọwọ ọtun mi, titi emi o fi sọ awọn ọta rẹ di apoti itisẹ rẹ. Njẹ ki gbogbo ile Israeli ki o mò dajudaju pe, Ọlọrun ti fi Jesu na, ti enyin kan mọ [igi] jẹ Oluwa ati Kristi [Ma-shi’ahh].”—Iṣe 2:1-36.

6. (a) Kini titu ti Jesu tú ẹmi na jade tumọsi nipa ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀? (b) Kini eyini tumọsi fun orilẹ-ede Israeli ati majẹmu Ofin rẹ̀?

6 Nipa bayi, nipa titu ẹmi mimọ lati ọdọ Ọlọrun jade sori awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ olotọ, Jesu nfi ororo yan wọn pẹlu ẹmi mimọ o si nkọ ijọ rẹ̀. Nigbana, kini eyi tumọsi fun orilẹ-ede Israeli, ti o ti kan Messiah tabi Kristi mọ igi? O tumọsi pe nwọn ki tun ṣe ijọ Jehofah Ọlọrun mọ. O tumọsi pe majẹmu Ofin wọn lailai ti di asan. A ti fagi le e, Ọlọrun funrarẹ̀ si kàn a mọ igi, lọna apẹrẹ, ori eyiti a kàn Jesu Kristi mọ gẹgẹ bi ẹ̀gún fun orilẹ-ede Israeli li ọjọ Irekọja. (Kolosse 2:13, 14; Galatia 3:13) Nipa titẹwọgba. Ọmọ Ọlọrun gẹgẹbi Messiah wọn ti a fi rubọ, awọn Ju ti a bi labẹ majẹmu Ofin le jade wa kuro labẹ ẹ̀gún rẹ̀ ki nwọn si ri ibukun Jehofah Ọlọrun gba.—Iṣe 3:25, 26.

7, Kini Jesu ṣe alarina rẹ̀ nisisiyi nipasẹ ẹjẹ rẹ̀, ipo wo li eyi si fi orilẹ-ede Israeli nipa ti ara si?

7 Siwaju si, nigbati Jesu Kristi fi lelẹ niwaju Baba rẹ̀ ọrun iniyelori tabi itoye iwaláyè ẹjẹ enia rẹ̀, o fidi majẹmu titun kan lelẹ, majẹmu ti a ṣeleri ninu Jeremiah 31:31-34. Gan gẹgẹ bi Mose ti ṣe alarina majẹmu Ofin lailai pẹlu ẹjẹ awọn ẹran irubọ lasan, bẹ gẹgẹ ni nisisiyi Jesu Kristi niwaju Ọlọrun ṣe alarina majẹmu titun pẹlu ẹjẹ irubọ ontikararẹ̀. Li ọna bayi pẹlu on jẹ Woli kan bi Mose. (Deuteronomi 18:15-18) Nitorina majẹmu titun kan ti rọpo majẹmu Ofin lailai na, orilẹ-ede Israeli nipa ti ara ko si si ninu majẹmu titun na. Nitorina orilẹ-ede na ko tun jẹ ijọ Jehofah Ọlọrun mọ, ko tun jẹ “Israeli Ọlọrun” mọ. Nitorina gbogbo awọn Ju nipa ti ara ti a bi lati igba imukuro majẹmu Ofin na koiti si labẹ majẹmu lailai na, biotilẹjẹpe awọn olukọni wọn le wipe nwọn wa ninu rẹ̀.

8. Iru Israeli wo li o bọ si ojutaiye li ọjọ Pentikosti, bawo ni Peteru si ti fihan iyatọ larin rẹ̀ ati Israeli nipa ti ara?

8 Pẹlu ọjọ Pentikosti ti 33 C.E. na, “Israeli Ọlọrun” kan nipa ti ẹmi bẹrẹ iwaláyé, ti a kọ lori Messiah na, Jesu gẹgẹ bi apata ipilẹ. “Nitoripe” gẹgẹ bi Galatia 6:15, 16 ti wi, “ninu Kristi Jesu ikọla ko jẹ ohun kan, tabi aikọla, bikoṣe ẹda titun. Iye awọn ti o si nrin gẹgẹ bi iwọn yi, alafia lori wọn ati anu, ati lori Israeli Ọlọrun.” Ni fifi iyatọ ti o wà lárin awọn wọnyi ati orilẹ-ede na ti o kọ Messiah na Jesu silẹ, aposteli Peteru kọwe si awọn ọmọ-ẹhin Messiah na wipe: “Ṣugbọn ẹnyin ni iran ti a yan, olu-alufa, orilẹ-ede mimọ, enia ọtọ; ki ẹnyin ki o le fi ọla nla ẹniti o pe nyin jade kuro ninu okunkun sinu imọlẹ iyanu rẹ̀ han.?”—1 Peteru 2:8, 9.

9. Onjẹ alẹ titun wo ni Jesu bẹrẹ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, majẹmu wo li on si sọrọ nipa rẹ̀?

9 Nitoripe ko si labẹ majẹmu Ofin Mose, “Israeli Ọlọrun” nipa ti ẹmi yi ko ṣe ajọ̀dun Irekọja li ọdọdun. Nigbati o pari Irekọja ikẹhin ti Jesu ṣe ajọyọ rẹ̀ pẹlu awọn aposteli rẹ̀ ni Jerusalemu, Jesu mu akara alaiwu ati ife waini kan o si bẹrẹ onjẹ alẹ ọdọdun titun kan fun awọn ọmọlẹhin rẹ ni iranti iku on tikararẹ̀ gẹgẹ bi Ọdọ agutan Ọlọrun ati gẹgẹ bi Alarina majẹmu titun na. Lẹhinti o ti gbadura sori ife waini na, o wi fun awọn aposteli olotọ rẹ̀ pe: “Gbogbo nyin ẹ mu ninu rẹ̀. Nitori eyi Itumọsil ẹjẹ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọpọ enia fun imukuro ẹṣẹ.” (Matteu 26:27, 28; fiwera pẹlu Eksodu 24:8.) Ṣugbọn majẹmu wo ni Jesu nsọrọ nipa rẹ̀? Akọsilẹ awọn ọrọ Jesu ti Luku kọ sọ fun wa, pe: “Ago yi ni majẹmu titun li ẹjẹ mi, Pe a ta silẹ fun nyin.”—Luku 22:20; 1 Korinti 11:20-26.

10. Bawo ni majẹmu na ti ri ni ifiwera pẹlu eyiti Mose ṣe alarina rẹ̀, esitiṣe ti a ko fi mu awọn Ju kan nipa ti ara ti a si kọ ni ila wọ̀ inu majẹmu titun na?

10 “Majẹmu titun” na ni gẹgẹ bi a ti sọ ọ tẹlẹ ninu Jeremiah 31:31-34 eyiti a o fi ẹjẹ Jesu fi idi rẹ̀ mulẹ, lati mu idariji ẹṣẹ Ọlọrun wa fun ẹṣẹ awọn wọnni ti a mu wọ inu majẹmu titun na. Majẹmu titun yi ni Jesu fidi rẹ̀ mulẹ nigbati o fi iniyelori tabi itoye ẹjẹ rẹ̀ lelẹ niwaju Jehofah Ọlọrun lẹhinti o ti goke re ọrun. Nipa eyi on di Alarina majẹmu titun na, eyiti o jẹ majẹmu ti o daraju eyiti Mose ṣe alarina rẹ ni Oke Sinai ni 1513 B.C.E. (Heberu 8:6-13; 9:15-20; 12:24; 13:20; 1 Timoteu 2:5, 6) O bani ninujẹ pe awọn Ju nipa ti ara ti a kọ ni ila ti o kọ lati tẹwọgba Jesu gẹgẹ bi Messiah li a ko mu wọ inu majẹmu titun na, nitorina nwọn ko jẹ apakan “Israeli Ọlọrun” nipa ti ẹmi.

11. Nibi onjẹ alẹ titun na, kini Jesu wi fun awọn aposteli rẹ̀ nipa ijọba kan, iyọrisi rere wo li eyi si mu daju fun majẹmu titun na?

11 Lẹhinti Jesu ti mu ki awọn aposteli rẹ̀ mu ago waini na ti o duro fun ẹjẹ rẹ̀ ti a nilati lo fun majẹmu titun na, o mba a lọ lati ba wọn sọrọ o si wipe: “Ẹnyin li awọn ti o ti duro tì mi ninu idanwo mi. Mo si yan ijọba fun nyin, gẹgẹ bi Baba mi ti yan fun mi; ki ẹnyin ki o le ma jẹ, ki ẹnyin ki o si le ma mu lori tabili mi’ni ijọba mi, ki ẹnyin ki o le joko lori itẹ, ati ki ẹnyin ki o le má ṣe idajọ fun awọn ẹya Israeli mejila.” (Luku 22:28-30) Eyiyi jẹ idaniloju kan pe majẹmu titun na ti a fidi rẹ̀ mulẹ nipasẹ ẹjẹ Jesu yio yọrisi rere ni mimu jade “ijọba alufa ati orilẹ-ede mimọ” kan. Awọn memba olotọ “Israeli Ọlọrun” ti a mu wọ inu majẹmu titun na yio ṣe alabapin pẹlu Jesu Kristi ninu ijọba ọrun eyiti yio ṣakoso lori eyiti o ju agbegbe ilẹ aiye lọ ti o jẹ ti Ọba Dafidi. Awọn wọnyi yio si ṣiṣẹ pẹlu gẹgẹ bi alufa ọmọ abẹ Oluwa Jesu Kristi, ẹniti a nilati sọ di “alufa titi lai nipa ẹsẹ ti Melkisedeki!”—Orin Dafidi 110:4.

A ṢI OHUN IJINLẸ NIPA “IRU-ỌMỌ” ABRAHAMU PAYA

12Niwọnbi ohun ijinlẹ na ti wà lati igba majẹmu ileri Ọlọrun fun Abrahamu babanla na lọhun ni 1943 B.C.E., Tani yio parapọ jẹ “iru-ọmọ” Abrahamu ti a ṣeleri na, fun bibukun gbogbo idile aiye? (Genesisi 12:1-3) Li ọjọ Pentikosti 33 C.E., a ṣí ohun ijinlẹ na paya. Apapọ “iru-ọmọ” na nilati ju Jesu Messiah nikan lọ, biotiwukiori, nitoripe Ọlọrun ti ṣeleri fun Abrahamu pe iru-ọmọ rẹ̀ yio dabi irawọ oju ọrun ati yanrin eti okun. Nitotọ, Israeli nipa ti ara ti a kọ nila dabi bẹ, ṣugbọn iru-ọmọ Abrahamu totọ nilati jẹ apapọ, ki iṣe ti Israeli nipa ti ara, bikoṣe ti Israeli nipa ti ẹmi, ti a fi ẹmi Ọlọrun bi lati di ọmọ Ọlọrun ti ẹmi pẹlu ijogun ti ọrun li ọkàn. Ọlọrun ni Abrahamu Titobiju, orukọ na si tumọsi “Baba Ogunlọgọ.”

13. Ni Pentikosti, tani a fun li anfani na lati jẹ apakan “iru-ọmọ” Abrahamu ti ẹmi, bawo li a si ti nawọ anfani yi jade pẹ to fun awọn nikan, esitiṣe?

13 Sugbọn, awọn enia Israeli nipa ti ara li a kọkọ fun li anfani lati di memba “iru-ọmọ” Abrahamu nipa ti ẹmi. Li ọjọ Pentikosti ti 33 C.E. awọn Ju nipa ti ara, ti a kọ nila, awọn atọmọdọmọ Abrahamu nipa ti ara li a fi ẹmi Ọlọrun bi gẹgẹ bi awọn ọmọ Rẹ̀ ti a si mu wọn wọ inu majẹmu titun na. Nipa bẹ Jehofah Ọlọrun di Abrahamu Titobiju fun “iru-ọmọ” ti ẹmi yi. Biotilẹjẹpe orilẹ-ede Israeli lọwọ ninu kike Messiah na kuro ninu iku ni arin ‘ọsẹ adọrin ọdun’ na (lati 29 si 36 C.E.), sibẹ Jehofah Ọlọrun mba a lọ lati fi ojurere han si wọn fun ilaji ọsẹ adọrin ti o ṣiku nitori bibu ọla fun majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, ẹniti orilẹ-ede Israeli jẹ atọmọdọmọ rẹ̀ nipa ti ara. (Danieli 9:24-27) Nitorina anfani lati di “iru-ọmọ” Abrahamu ti ẹmi ntẹsiwaju lati di ohun ti a kọkọ nawọ rẹ̀ si wọn titi de opin ọsẹ adọrin.

14. Bawo ni Peteru, ni tempili ni Jerusalemu, ṣe tọka si ipese oninure yì fun iru-ọmọ Abrahamu nipa ti ara?

14 Ọjọ diẹ lẹhin Pentikosti aposteli Peteru tọkasi ipese oninure Ọlọrun yi, nigbati o mba awujọ awọn Ju sọrọ ni tempili Jerusalemu: “Ani gbogbo awọn woli lati Samueli wa, ati awọn ti o tẹle e, iye awọn ti o ti sọrọ, nwọn sọ ti ọjọ wọnyi pẹlu. Ẹnyin li ọmọ awọn woli, ati ti majẹmu ti Ọlọrun ti ba awọn baba nyin dá nigbati o wi fun Abrahamu pe, Ati ninu iru-ọrọ rẹ li a o ti fi ibukun fun gbogbo idile aiye. Nigbati Ọlọrun ji [Iranṣẹ] rẹ̀ dide, o kọ ran a si nyin lati busi i fun nyin, nipa yiyi olukuluku nyin pada kuro ninu iwa buburu rẹ̀.”—Iṣe 3:24-26.

15. Tani, nigbana, ni ibukun “iru-ọmọ” Abrahamu kọkọ de ọdọ rẹ̀, bawo li a si ṣe dá awọn wọnni ti a bukun nídè kuro li oko ẹrú?

15 Ọdun diẹ lẹhinna Farisi kan tẹlẹri, ti o ti saba má njẹ onitara fun awọn ẹkọ atọwọdọwọ awọn Ju, kọ ọrọ wọnyi:

“Kristi [Ma.shi’ahh] ti rà wa pada kuro lọwọ ẹ̀gún ofin, ẹniti a fi ṣe ẹgún fun wa: nitoriti a ti kọ ọ pe, Ifibu li olukuluku ẹniti a fi kẹ sori igi. Ki ibukun Abrahamu ki o le wá sori awọn Keferi nipa Kristi Jesu; ki awa ki o le gba ileri ẹmi nipa igbagbọ.”

“Sugbọn nigbati akoko kikun na de, Ọlọrun ran Ọmọ rẹ̀ jade wa, ẹniti a bi ninu obirin, ti a bi labẹ ofin, lati ra awọn ti mbẹ labẹ ofin pada, ki awa ki o le gba isọdọmọ. Ati nitoriti ẹnyin nṣe ọmọ, Ọlọrun si ti rán ẹmi Ọmọ rẹ̀ wà sinu ọkàn nyin, ti nke pe, Abba, Baba. Nitorina iwọ ki iṣe ẹrú mọ, bikoṣe ọmọ; ati bi ìwọ ba iṣe ọmọ, njẹ ìwọ di arole Ọlọrun nipasẹ Kristi.”—Galatia 3:13, 14; 4:4-7.

16. Jijẹ ti ẹnikan jẹ memba “iru-ọmọ” Abrahamu ti ẹmi la gbeka ori ibatan nipa ti ara, tabi lori kini?

16 Ni ṣiṣe alaye pe jijẹ memba ninu “iru-ọmọ Abrahamu” li a ko gbeka ori nini ibatan pẹlu Abrahamu nipa ti ara bikoṣe fifi igbagbọ han gẹgẹ bi Abrahamu ti ṣe, akọwe ti a ṣẹṣẹ ka ọrọ rẹ̀ tan yi, aposteli Paulu, wipe: “Nitorina ìri ẹnyin ki o mọ pe awọn ti iṣe ti igbagbọ, awọn na ni iṣe ọmọ Abrahamu. Bi iwe mìmọ, si ti ri i tẹlẹ pe, Ọlọrun yio da awọn Keferi lare nipa igbagbọ, o ti wasu ihinrere ṣaju fun Abrahamu, o nwipe, Ninu rẹ li a o bukun fun gbogbo orilẹ-ede. Nitoripe ọmọ Ọlọrun ni gbogbo nyin, nipa igbagbọ ninu Kristi Jesu. Nitoripe iye ẹnyin ti a ti baptisi sinu Kristi, ti gbe Kristi wọ. Ko le si Ju tabi Griki, ẹru tabi ominira, ọkunrin tabi obirin: nitoripe ọkan ni gbogbo nyin jẹ ninu Kristi Jesu. Bi ẹnyin ba si jẹ ti Kristi, njẹ ẹnyin ni iru-ọmọ Abrahamu, ati arole gẹgẹ bi ileri.”—Galatia 3:7, 8, 26-29: Genesisi 12:3.

OHUN IJINLẸ KAN ṢI AWỌN IRAN PAYA LẸHINNA

17. Awọn Ju melo li o ni igbagbọ bi ti Abrahamu ti nwọn si lo anfani ‘adọrin ọsẹ ọdun’ ti ojurere atọrunwa fun wọn?

17 Ki iṣe gbogbo atọmọdọmọ Abrahamu li o ni igbagbọ ti on ni ti o si yọrisi pipe ti a pe e ni olododo ati “ọrẹ” Ọlọrun ani ṣaju ki a to kọ ọ ni ila ninu ara. (Genesisi 15:6; Romu 4:9-12: Jakobu 2:21-23) Nitorina ki iṣe pupọ ninu awọn Ju nipa ti ara li o lo anfani ‘adọrin ọsẹ ọdun’ na nigbati majẹmu Abrahamu ‘si nṣiṣẹ’ nitori atọmọdọmọ Abrahamu nipa ti ara, Isaaki ati Jakobu. (Danieli 9:27) Kiki iyoku kekere kan li o ṣe bẹ, Iye ti o kẹhin fun awọn Ju wọnni ni Jerusalemu ti o tẹwọgba Messiah Jesu ki opin ‘adọrin ọsẹ ọdun’ to pe ni 36 C.E. li a sọ pe o to nkan bi ẹgbẹdọgbọn.—Iṣe 4:4.

18. Melo li Ọlọrun pete lati ni fun Israeli ti ẹmi, nitorina awọn ibere wo li o dide li opin ‘adọrin ọsẹ̀’?

18 Ọlọrun ti pinnu tẹlẹ iye kan ti O tobi ju eyini lọ pupọpupọ fun “ijọba alufa ati orilẹ-ede mimọ” rẹ̀ eyiti majẹmu titun na yio mu jade. Iye na ti on pete lati ni li on ko fihanni titi di igba iparun Jerusalemu ni 70 C.E. ati li opin ọgọrun ọdun ekini. Nigbana fun aposteli Johannu arugbo ti mbẹ láyé li on fihan iye Israeli ti ẹmi ti on pete lati yan pe o jẹ 144,000. (Ifihan 7:4-8 ; 14-1-3) Nigbati ‘ọsẹ adọrin’ pari nigba ikore 36 C.E., iye awọn Ju ti o ti tẹwọgba Jesu gẹgẹ bi Messiah ti a si ti fi ẹmi mimọ baptisi dajudaju din pupọpupọ si 144,000. Kini nigbana? Ete Ọlọrun ha ti kuna? Tabi, kini igbesẹ yiyanilẹnu ti on yio gbe nisisiyi ki o maṣe jẹki “ete aiyeraiye” rẹ̀ ninu Kristi kuna?

19. Ifihan wo li Ọlọrun wa ṣe nisisiyi nipa ẹgbẹ awọn onigbagbọ ti a baptisi labẹ Jesu Messiah gẹgẹ bi Ori?

19 Titi di igba ikore 36 C.E. ijọ awọn ọmọlẹhin Messiah Jesu ti a baptisi jẹ kiki awọn Ju nipa ti ara nikan, awọn ara Samaria ti a kọ ni ila awọn miran ti nwọn ti di alawọṣe Ju ti a kọ ni ila. (Iṣe 2:10; 8:1 titi de 9:30; 11:19) Iyoku araiye jẹ awọn alaigbagbọ, “laini Kristi,” nwọn “jẹ ajeji si anfani awọn ọlotọ Israeli, ati alejo si awọn majẹmu ileri nì, laini ireti ati laini Ọlọrun li aiye.” (Efesu 2:11, 19) Nisisiyi ni ifihan kan de: Ẹgbẹ awọn onigbagbọ labẹ Messiah Jesu gẹgẹbi Ori wọn ko tun ni jẹ kiki awọn enia ti a mu jade lati inu iran Ju ati awọn alawọṣe Ju. Lati igba yi lọ a nilati mu wọ inu ẹgbẹ awọn ọmọlẹhin Messiah awọn onigbagbọ alaikọla, awọn enia ti a ko kọ nila gan gẹgẹ bi Abrahamu ti jẹ nigbati Ọlọrun pe e ti o si da majẹmu na pẹlu rẹ̀ ti o si da a lare lati di ọrẹ Ọlọrun nitori igbagbọ. Bẹ gẹgẹ, pẹlu, ni awọn ti ki iṣe Ju ti a tẹwọgba wọnyi ni igbagbọ.

20. (a) Nitorina kini ohun na ti ko nilati jẹ idena mọ larin Ju ati ẹniti ki iṣe Ju? (b) Nitorina tani Ọlọrun wa yi afiyesi olojurere si nisisiyi?

20 Li arin ‘adọrin ọsẹ’ ni 33 C.E., Ọlọrun ti mu majẹmu Ofin Mose kuro o si ti gbe “majẹmu titun” ti o daraju kalẹ pẹlu Israeli nipa ti ẹmi. Nitorina majẹmu Ofin lailai na ko nilati duro gẹgẹ bi idena larin Ju ati Keferi. Nitorina, ni gbigba ọna kan ti a tunṣe, gẹgẹ bi a ti sọ ọ ninu Efesu 2:13-18, Jehofah Ọlọrun yi afiyesi rẹ̀ pẹlu ojurere si awọn orilẹ-ede. Keferi ti a ko kọ nila ki o ba le “yan enia ninu wọn fun orukọ rẹ̀.”—Iṣe 15:14; Amosi 9:11, 12, Greek Septuagint Version.

21. Tani Ọlọrun rán angeli rẹ̀ si nigbana, ki si ni ohun ti ẹni yii se

21 Li opin adọrin ọsẹ ọdun na, Jehofah Ọlọrun rán angeli rẹ̀, si tani? Si Keferi alaikọla kan ni olu ilu gomina Romu ti nbojuto agbegbe Judea. Korneliu ni ọkunrin Keferi yi, balogun ọ̀rún ti ẹgbẹ ogun Itali, ṣugbọn o jẹ “olufọkansin, ati ẹniti o bẹru Ọlọrun tiletile rẹ̀ gbogbo, ẹniti ima tọrẹ-anu pipọ fun awọn enia, ti o si ngbadura sọdọ Ọlọrun nigba gbogbo.” Korneliu li a sọ fun pe ki o ranṣẹ lọ si iha gusu si etikun ilu Joppa ki o si mu Simoni Peteru wa lati ibẹ. Simoni Peteru ati awọn ọkunrin mẹta ti a ran si i si padabọ, a si ti sọ fun u pe ki o ba wọn lọ ki o si dẹkun lati pe “ohun ti Ọlọrun ba ti wẹnu!” “di ewọ̀ mọ.”

22. Ninu ile Keferi na, kini Peteru wásu nipa rẹ̀ fun awọn enia ti o korajọpọ, kini o si sọ nipa idariji ẹṣẹ?

22 Nitorina ni pipa ina ẹtanu rẹ̀ lodi si wiwọ ile Keferi kan, Simoni Peteru wọ̀ inu ile Korneliu ni Kesarea. Nigbati a kesi i o wasu fun Keferi yi ati awọn wọnni ti on ti kojọ sinu ile rẹ̀ lati gbọ ọrọ aposteli Peteru. Peteru wasu fun wọn nipa Messiah na ti Ọlọrun ti ran si Israeli. Peteru mba a lọ lati wipe, “O si pasẹ fun wa lati wasu fun awọn enia, ati lati jẹri pe, on li a ti ọwọ Ọlọrun yàn ṣe Onidajọ áyé on oku. On ni gbogbo awọn woli jẹri si pe, nipa orukọ rẹ̀ li ẹnikẹni ti o ba gba a gbọ, yio ri imukuro ẹṣẹ gba.”—Iṣe 10:1-43; 11:4-14.

23. Nigba iṣẹ iyanu wo ni Peteru paṣẹ ki a baptisi awọn olugbọ rẹ̀, li orukọ tani?

23 Awọn ọrọ wọnni ti to fun Korneliu ati awọn ti nfetisi i. Pẹlupẹlu, Ọlọrun ri ọkàn wọn o si ṣe nkankan. A kà pe:

“Bi Peteru si ti nsọ ọrọ wọnyi li ẹnu, ẹmi mimọ ba le gbogbo awọn ti o gbọ ọrọ na. Ẹnu si ya awọn onigbagbọ ti ikọla, iye awọn ti o ba Peteru wa, nitoriti a tú ẹbun ẹmi mimọ sori awọn Keferi pẹlu. Nitori nwọn gbọ, nwọn nfọ oniruru ede, nwọn si [nyìn] Ọlọrun logo. Nigbana ni Peteru dahun wipe, Ẹnikẹni ha le ṣofin omi, ki a má baptisi awọn wọnyi, ti nwọn gba ẹmi mimọ bi awa? O si paṣẹ ki a baptisi wọn li orukọ Jesu Kristi. Nigbana ni nwọn bẹ̀ ẹ ki o duro ni ijọ melokan.”—Iṣe 10:44-48; 11:1-17.

24. Kini awọn Ju wọnni ni Jerusalemu ti o gbọ alaye Peteru ṣe ni idahun si i?

24 Lẹhinna, nigbati o npadabọ wa si Jerusalemu, Peteru ṣalaye ọna rẹ̀ fun awọn Ju onigbagbọ ti a kọ ni ila, ti mbẹ nibẹ, wipe: “Njẹ bi Ọlọrun si ti fi iru ẹbun kanna fun wọn ti o ti fifun wa pẹlu nigbati a gba Jesu Kristi Oluwa gbọ, tali emi ti emi o fi le da Ọlọrun li ọna? Nigbati nwọn si gbọ nkan wọnyi, nwọn si pa ẹnu wọn mọ, nwọn si yìn Ọlọrun logo wipe, Njẹ Ọlọrun fi ironupiwada si iye fun awọn Keferi pẹlu.”—Iṣe 11:17, 18.

25. Aṣẹ wo ti Jesu ti a ji dide pa ni awọn Ju onigbagbọ ti a kọ nila ṣe igbọran si?

25 Lati igbana lọ, awọn aposteli ati awọn Ju onigbagbọ ẹlẹgbẹ ko fi ara wọn mọ si ọdọ kiki awọn Ju nikan ati awọn alawọṣe Ju, ṣugbọn nwọn ṣe ohun ti Jesu ti a ji dide sọ fun wọn lati ṣe: “Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ́”—tani?—“orilẹ-ede gbogbo, ki ẹ si má baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti ẹmi mimọ. Ki ẹ má kọ wọn lati má kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin: ẹ si kiyesi i, emi wa pẹlu nyin nigba gbogbo, titi o fi de opin aiye.”—Matteu 28:19, 20.

26. Aposteli wo ní pataki li o kọwe nipa ohun ijinlẹ Ọlọrun pẹlu itọka si awọn Keferi onigbagbọ?

26 Saju iyilọkanpada Korneliu si didi ọmọ-ẹhin Messiah na, Saulu ara Tarsu, ẹniti o ti jẹ oninunibini tọkantọkan fun awọn ti o gba Messiah gbọ ninu awọn Ju enia rẹ̀ funrarẹ̀, li a ti yi on tikararẹ̀ lọkan pada. Kiakia li o bẹrẹsi wasu fun awọn Ju onila miran, ti o nfi i han wọn lati inu Iwe Mimọ Heberu ti a misi pe Jesu yi, ọmọ Dafidi, ni Messiah na ti a sọtẹlẹ tabi Kristi. Nigbati o ṣe a fun u ni ipo oye aposteli a si npe e ni Paulu, ni pataki a si fi i ṣe “aposteli awọn keferi.” Ni pataki o kọwe nipa ohun ijinlẹ yiyanilẹnu kan, tabi “aṣiri mimọ,” ti Ọlọrun fihan nibẹ ni 36 C.E. nipa titẹwọgba awọn Keferi ti o gbagbọ sinu ẹgbẹ awọn ọmọ-ẹhin Kristi, gẹgẹ bi memba “iru-ọmọ Abrahamu.”—Romu 11:13.

27. “Ohun ijinlẹ” ọlọla wo ni Paulu nsọ di mimọ̀ larin awọn orilẹ-ede Keferi?

27 Fun apẹrẹ, Paulu kọwe nipa koko kan ti o wà ni ipamọ tipẹtipẹ nipa ijọ Messiah na: “Eyiti a fi emi ṣe iranṣẹ fun, gẹgẹ bi iṣẹ iriju Ọlọrun ti a fifun mi fun nyin lati mu ọrọ Ọlọrun ṣẹ. Ani ohun ijinlẹ [tabi, ohun ikọkọ] ti o ti farasin lati aiyeraiye ati lati irandiran, ṣugbọn ti a ti fihan nisisiyi fun awọn enia mimọ rẹ̀. Awọn ẹniti Ọlọrun fẹ lati fi ọrọ ohun ijinlẹ yi larin awọn Keferi han fun, ti iṣe Kristi ninu nyin, ireti ogo.” (Kolosse 1:25-27) Iru “ohun ijinlẹ” ọlọla wo li eyi, ti a fihan lẹhin igba akoko pipẹ bẹ, pe awọn onigbagbọ lati inu awọn orilẹ-ede Keferi nilati di ẹniti a fun ni “ireti” ọrun ti iṣelogo pẹlu Messiah na, Kristi! Dajudaju o jẹ ọlá kan ati anfani kan lati jẹ ojiṣẹ kan fun ìjọ kan ti o ni iru ireti kan bẹ!

28, 29. (a) Igbati-ẹni-ro onifẹ yi fun awọn Keferi onigbagbọ wà ninu ete Ọlọrun nipa awọn tani? (b) Ni fifi ọpẹ han fun ipa tirẹ̀ ninu eyi, kini Paulu kọwe rẹ̀ nipa “ete aiyeraiye” Ọlọrun?

28 A! ki a ṣa ronu pe ijiroro gbogbo ipese onifẹ yi wà ninu ete giga na ti Ọlọrun gbekalẹ niti Messiah rẹ̀, lati le mu ki awọn Keferi onigbagbọ jẹ apakan “iru-ọmọ” Abrahamu ti ẹmi fun bibukun gbogbo araiye! Bawo li o ti wuni to pe Ọlọrun onifẹ yi ti rọ̀ mọ́ apa ọlọlawọ yi ninu ifẹ rẹ̀, nitoripe o jẹ apakan “ete aiyeraiye” rẹ̀! Ni fifi imọriri han fun apa ti Ọlọrun fifun u nipa eyi, Paulu wipe:

29 “Fun emi ti o kere ju ẹniti o kere julọ ninu gbogbo awọn enia mimọ, li a fi ore-ọfẹ yi fun, lati wasu awamaridi ọrọ Kristi fun awọn Keferi. Ati lati mu ki gbogbo enia ri kini iṣẹ iriju ohun ijinlẹ na jasi, eyiti a ti fi pamọ lati aiyebaiye ninu Ọlọrun, ẹniti o dá ohun gbogbo nipa Jesu Kristi. Ki a le ba fi ọpọlọpọ onirúru ọgbọn Ọlọrun han nisisiyi fun awọn ijoye ati awọn alagbara ninu awọn ọrun, nipasẹ ijọ. Gẹgẹ bi ipinnu [Griki: pro’the’sis] ataiyebaiye ti o ti pinnu ninu Kristi Jesu Oluwa wa.”—Efesu 3:8-11.

30. (a) Gẹgẹ bi “ete aiyeraiye” Rẹ̀, bawo li Ọlọrun ṣe tẹsiwaju lati sọ di mimọ̀ “ọpọlọpọ oniruru ọgbọn” rẹ̀? (b) Eṣe ti a fi ṣe ojurere si wa pupọpupọ ju lati waláyé li akoko yi?

30 Nipa bayi Ọlọrun ntẹsiwaju ni ọna bẹ pẹlu. “ohun ijinlẹ” rẹ̀ pe, “gẹgẹ bi ipinnu ataiyebaiye ti o ti pinnu ninu Kristi,” ki a le fihan nisisiyi li akoko yi fun awọn ijọba ati awọn ijoye ti mbẹ li ọrun “ọpọlọpọ oniruru ọgbọn Ọlọrun” nipa imujade ijọ Kristian gẹgẹ bi apẹrẹ kan nibẹ. A ko ha ṣe ojurere si wa pupọ ju lati le waláyé li akoko liloye “ohun ijinlẹ” Ọlọrun gẹgẹ bi “ipinnu ataiyebaiye” rẹ̀? Paulu wipe:

“Eyiti a ko ti fihan awọn ọmọ enia ri ni irandiran miran, bi a ti fihan nisisiyi fun awọn aposteli rẹ̀ mimọ ati awọn woli nipa ẹmi. Pe, awọn ti ki iṣe Ju jẹ alabajogun ati ẹya-ara kanna ati alabapin ileri ninu Kristi Jesu nipa ihinrere.”—Efesu 3:5, 6.

31, 32. (a) Tani, ṣaju awọn akoko Kristi li o ni ifẹ si liloye awọn nkan wọnyi? (b) Nitorina lati inu tani li ao ti mu “ara” Kristi jade?

31 Awọn woli igbánì ti o ti wà ṣaju Kristi, bẹni, ani awọn angeli pápá, ní ifẹ si bi Jehofah Ọlọrun yio ṣe bojuto “ohun ijinlẹ” yi.

“Igbala ti awọn woli wadi, ti nwọn si wá. jinlẹ, awọn ti nwọn sọ asọtẹlẹ ti ore-ọfẹ ti mbọ fun nyin. Nwọn nwadi igba wo tabi iru sí wo ni ẹmi Kristi ti o wà ninu wọn ntọka si, nigbati o jẹri iya [ti a yan tẹlẹ, ni ipamọ] Kristi tẹlẹ ati ogo ti yio tẹle e. Awọn ẹniti a fihan fun, pe ki iṣe fun awọn tikarawọn, bikoṣe fun awa ni nwọn ṣe iranṣẹ ohun wọnni, ti a rohin fun nyin nisisiyi, lati ọdọ awọn ti o ti nwasu ihinrere fun nyin pẹlu ẹmi mimọ ti a rán lati ọrun wa; ohun ti awọn angeli nfẹ lati wo.”—1 Peteru 1: 10-12, NW; An America Translation.

32 Nitorina nigbati akoko Ọlọrun to a fihan pe iye kikun memba “ara” Kristi yio jẹ apapọ awọn Keferi ati awọn Ju. “Ete aiyeraiye” Ọlọrun, gẹgẹ bi a ti kọkọ gbe e kalẹ ninu Ọgba Edeni, fi ijọ yi si ọkan ti o ni Messiah gẹgẹ bi Ori rẹ̀. Ninu rẹ̀ awọn Ju ati awọn Keferi li a sopọ sọkan.

[Ibeere]

12. Ni Pentikosti 33 C.E., ohun ijinlẹ wo li a ṣipaya nipa ti “iru-ọmọ” Abrahamu, “iru-ọmọ” wo li o si nilati jẹ?