Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Seto “Ete Aiyeraiye” Ọlọrun ninu Ẹni Ami Ororo Rẹ̀

A Seto “Ete Aiyeraiye” Ọlọrun ninu Ẹni Ami Ororo Rẹ̀

Ori 5

A Ṣeto “Ete Aiyeraiye” Ọlọrun ninu Ẹni Ami Ororo Rẹ̀

1. Iru igbesi aiye wo lori ilẹ aiye li o jẹ ete Ọlọrun fun araiye lati ní?

IGBESI aiye enia lori ilẹ aiye le lẹwa. Igbesi aiye enia ti Ẹlẹda dá jẹ ẹlẹwa. O jẹ ifẹ Rẹ̀ pe igbesi aiye enia Rẹ̀ ti on dá ki o lẹwa pẹlu. Araiye li o ti sọ iwalãyè rẹ̀ di ibajẹ. Ki iṣe gbogbo memba araiye li o ti ṣe bẹ, biotiwukiori. Laika ikuna araiye titi di isisiyi si, ete alanfani Ẹlẹda na nisisiyi ni pe ki awọn ọkunrin ati obirin ní anfani sibẹ lati mu igbesi aiye lori ilẹ aiye lẹwa fun ara wọn.

2. (a) Pẹlu iru igbesi aiye wo ni araiye fi bẹrẹ? (b) Kini fihan boya Ọlọrun wewe fun enia lati gba ọna ti o yọrisi iku?

2 Ni ibẹrẹ, igbesi aiye enia lẹwa. O bẹrẹ ni nkan bi ẹgbáta ọdun sẹhin ninu Paradise kan lori ilẹ aiye. O jẹ igbadun lati gbe nibẹ, eyiti o si jẹ idi ti a fi pee ni Ọgba Edeni, tabi Paradise Igbadun, (Genesisi 2:8, Bibeli Douay Version) Awọn enia obi wa akọkọ, ọkunrin ekini ati obirin ekini, jẹ pipe, nwọn si kun fun ilera ati ireti aiku titi lai. Nitoripe nwọn jẹ enia, nwọn jẹ ẹniti o le ku, ṣugbọn niwaju wọn ni anfani wà ti Ẹlẹda wọn fifun wọn lati gbe inu Paradise Igbadun fun gbogbo igba ti mbọ, aiyeraiye. Nipa bayi, Olufunni-ni-Iye wọn ti mbẹ li ọrun le jẹ Baba wọn Aiyeraiye. On ko wewe fun wọn lati ku nipa titẹle ọna ti yio yọrisi iku. Ifẹ rẹ̀ fun wọn ni lati wà titilai gẹgẹ bi awọn ọmọ rẹ̀ aiyeraiye. Ni eyiti o ju ẹgbẹdogun ọdun lẹhinna, On fi awọn ero rẹ̀ atọkanwa han lori ọran na, nigbati on sọ fun awọn enia rẹ̀ ayanfẹ pe:

“‘Emi ha ni inu-didun rara pe ki enia buburu ki o ku? ni [Jehofah] Ọlọrun wi: ko ṣepe ki o yipada kuro ninu ọna rẹ̀, ki o si yé?’”—Esekieli 18:23.

3. Niwọnbi ifẹ Ọlọrun fun araiye ti jẹ lati má waláyé niṣo ninu Paradise, ibere wo li a fi agbara mú wá sori wa loni?

3 Nitorina Ẹlẹda na ko ni ifẹ pe ki tọkọtaya alailẹṣẹ na ninu Paradise Igbadun yipada di “buburu” ki nwọn si yẹ fun iku. Ifẹ rẹ̀ fun wọn ni lati má wà láyè niṣo, bẹni, ki nwọn wà láyé lati ri ki gbogbo ilẹ aiye kún fun awọn ọmọ, ki nwọn pé ki nwọn si layọ gan gẹgẹ bi awọn, ninu ibatan alalafia, onifẹ pẹlu Ẹlẹda wọn, Baba wọn ọrun. Sibẹ, loni, gbogbo araiye li o nkú, ilẹ aiye ti o si ti di o lé rùn jinna si jijẹ paradise kan. Eṣe ti eyi fi ri bẹ? Ẹlẹda enia ti ni alaye rẹ̀ ti a kọ sinu Bibeli.

4. Eṣe ti o fi ṣajeji fun ejo kan lati sọ ara rẹ̀ di ohun ti a le rì fun enia kan ninu Paradise?

4 Ibẹ ni Paradise Igbadun, gẹgẹ bi Bibeli ti ṣe bẹrẹ rẹ̀ ninu ori kẹta ninu iwe Genesisi. Oniriru gbogbo awọn ẹda rirẹlẹ lori ilẹ aiye li o wà labẹ akoso Adamu ati Efa, awọn enia obi wa akọkọ. Nwọn ko bẹru eyikeyi ninu awọn ẹda rirẹlẹ lori ilẹ aiye wọnyi, ki a má tilẹ sọ ti ejo. Bẹni, awọn ejo wà ninu Paradise Igbadun, nwọn si gbadun mọni lati wò. Irin wọn laisi ẹsẹ yanilẹnu, ifihan ọgbọn Ọlọrun ni ọkan-ko-ju- kan ninu iṣeto. Biotiwukiori, nwọn jẹ ẹda ti ntiju. Genesisi 3:1 ṣalaye lori iru ẹran ẹlẹ́jẹ̀-tutu yi, wipe: Ejo [na-hhash] sa ṣe arekereke ju ẹranko igbẹ iyoku lọ ti [Jehofah] Ọlọrun ti dá.” Nitorina dipo ki o lumọ lati ṣe enia ni jamba, yio ni itẹsi lati fi ara rẹ̀ pamọ kuro ninu nini nkan iṣe pẹlu enia. Ṣugbọn nisisiyi, pẹlu iyalẹnu, a ri i kedere, yala lori ilẹ tabi lori igi. Eṣe?

5. Eṣe ti o fi ṣajeji pe ejo na bere ibere kan lọwọ Efa, esitiṣe ti ko fi jẹ ohùn Ọlọrun laiṣe táràtà?

5Genesisi 3:1 mba a lọ: “O si wi fun obirin na pe, Òtọ li Ọlọrun wipe, Ẹnyin ko gbọdọ jẹ gbogbo eso igi ọgba?” O dara, nisisiyi, bawo ni ejo na ṣe gbọ iru nkan bẹ? Tabi bawo li on ṣe loye iru nkan bẹ? Pẹlupẹlu, bawo li o ṣe jẹ pe on koiti ba Adamu ọkọ obirin na sọrọ ri? Bawo li o ṣe jẹ pe o le sọrọ li ede enia rara? Ejo koiti ba enia sọrọ ri, ko si ti ṣe bẹ ri lati igba na. Efa ko ronu pe ẹnikan mba on sọrọ. On ko ba ara rẹ̀ sọrọ ninu ọkàn rẹ̀, ki o ronu lasan. Ohùn ti o dabi ti enia na dabi ẹnipe o nwa lati ẹnu ejo na. Bawo li eyini ṣe le ri bẹ? Kiki ohùn miran yatọ si ti Adamu ọkọ rẹ̀ ti Efa ti gbọ ri ninu ọgba na ni ti Ọlọrun, ṣugbọn ni táràtà li eyi jẹ, ki iṣe nipasẹ ẹda ẹranko kan ti ki iṣe enia. Bi gbogbo nkan ti fara han, gẹgẹ bi ohun ti ejo na wi, ohùn na bere lọwọ Efa ohun ti Ọlọrun wi.

6. Li ọna wo ni onibere na ti o lo ejo na lati bere ibere na gba huwa, Eṣe ti Efa si fi dahun?

6 Nigbati Efa dahun ibere na, on nsọrọ, ki iṣe si ejo na, ṣugbọn si oloye kan ti a ko le fojuri ti o nlo ejo na gẹgẹ bi ọmọlangidi kan. Oloye asọrọ ti a ko le fojuri yi ha iṣe ọrẹ Ọlọrun tabi odikeji rẹ̀? Dajudaju ọna ti asọrọ ti a ko le fojuri na gba ni sisọrọ si Efa jẹ ti ẹtan, ti o nsún u lati ronu pe ejo na li o nṣiṣẹ ọrọ na. Olubanisọrọ ti mbere ibere na nfi ara rẹ̀ pamọ sẹhin ejo kan ti a le fojuri, nipa bayi o nṣiṣẹ ẹtan. Ṣugbọn, Efa ko ṣakiyesi ki o si mọriri pe asọrọ ti nlo ejo yi nfi ifẹ buburu tàn a. Laifura Efa sọ idahun rẹ̀.

“Obirin na si wi fun ejo na pe, ‘Awa a ma jẹ ninu eso igi ọgba. Ṣugbọn ninu eso igi nì ti o wà Iarin ọgba Ọlọrun ti wipe, “Ẹnyin ko gbọdọ jẹ ninu rẹ̀, bẹli ẹnyin ko gbọdọ fọwọkan a, ki ẹnyin ki o má ba ku.”’”—Genesisi 3:2, 3.

7. Nibo ni Efa ti ri ọrọ rẹ̀ lori igi ti o wà lárin ọgba na?

7 Nipa fifi i han kedere gẹgẹ bi ’igi ti o wà larin ọgba,” Efa ni igi imọ rere ati buburu lọkan. Ṣugbọn bawo li Efa ṣe mọ nipa igi na? O ti nilati jẹ pe Adamu, gẹgẹ bi woli Ọlọrun, ti sọ fun u. On li ẹniti Ọlọrun sọ fun nigbati Adamu ṣi dá nikan wà, ṣaju iṣẹda Efa pe: “Ninu gbogbo igi ọgba ni ki iwọ ki o má jẹ: Ṣugbọn ninu igi imọ rere ati buburu nì, iwọ ko gbọdọ jẹ ninu rẹ̀: nitoripe li ọjọ ti iwọ ba jẹ ninu rẹ̀ kiku ni iwọ o ku.” (Genesisi 2:16, 17) Gẹgẹ bi Efa ti wi, Ọlọrun si sọ pẹlu pe ko si fifi ọwọ kan eso igi ti a kaléwọ na. Nitorina Efa ko ṣaimọ ijiya fun riru ofin Ọlọrun. Iku ni.

8. Kini fihan boya onibere ti a ko ri na wulẹ nbere fun isọfunni?

8 Bi asọrọ ti a ko le fojuri na lẹhin ejo na ba ti bere fun isọfunni siwaju si i ni, on iba ti jawọ kuro ninu ifọrọwerọ na lẹhinti a ba ti sọ fun u. Boya, li akoko yi, ejo na wà lárin ọgba na nibiti igi ti a kaléwọ na wà, boya ejo na si wà lori ilẹ tabi loke lori igi, a ko sọ. O kere o pọ, ọrọ na jẹ nipa igi na “ti o wà lárin ọgba.”

9, 10. Bawo ni asọrọ ti a ko ri na lẹhin ejo na fi jẹ eleke kan, Eṣu kan, Satani kan, fun ara rẹ̀?

9 Bawo ni ejo kan lasan ṣe mọ tabi ni ọla aṣẹ lati sọ ohun ti Efa gbọ nisisiyi? “Ejo na si wi fun obirin na pe, Ẹnyin ki yio ku iku kiku kan. Nitori Ọlọrun mọ pe, li ọjọ ti ẹnyin ba jẹ ninu rẹ̀, nigbana li oju nyin yio là, ẹnyin o si dabi Ọlọrun, ẹ o si mọ rere ati buburu.”—Genesisi 3:4, 5.

10 Nihin li asọrọ ti a ko le ri na lẹhin ejo ti a le ri na nsọ ara rẹ̀ di opurọ, nitoripe on ntako Jehofah Ọlọrun. Nipa kikede pẹlu ariwo pe Ọlọrun ni ete ti o lodi fun kikà a léwọ fun Adamu ati Efa lati jẹ ninu eso igi imọ rere ati buburu, asọrọ ti a ko le ri na nsọ ara rẹ̀ di abanijẹ, Eṣu, si Jehofah Ọlọrun. On ko fi ifẹ han si iye aiyeraiye Efa, ṣugbọn o npetepero lati mu iku rẹ̀ wa. Niti tôtọ, o ngbiyanju lati mu ibẹru iku kuro lọdọ rẹ̀, ki iṣe iku lati ọwọ rẹ̀, ṣugbọn iku lati ọwọ Jehofah Ọlọrun fun riru ofin rẹ̀ ti on ti mọ̀. Asọrọ ti a ko le ri na ngbe ara rẹ̀ kalẹ li atako si Ọlọrun o si tipa bayi nsọ ara rẹ̀ di Satani, eyiti o tumọsi Alatako. On ni ifẹ si mimu ki ẹlomiran tako Ọlọrun ki o si fi ẹlomiran si iha ọdọ Satani. Awa mọ ẹniti iru asọrọ eke ati abanijẹ bẹ jẹ. Ki iṣe ejo kankan!

11. Bawo ni Efa nisisiyi ko fi fi iṣotitọ han si Ọlọrun ati ọwọ fun ọkọ rẹ̀, ti o si jẹki a dán an wò?

11 O baninujẹ pe, Efa ko jiyàn irọ pipa yi, gbolohun ọrọ ibanijẹ yi. On ko fi tifẹtifẹ ati pẹlu iṣotitọ wá si igbeja Baba rẹ̀ ọrun. On ko tẹwọgba nisisiyi jijẹ ti Adamu ọkọ rẹ̀ jẹ olori rẹ̀ ki o si tọ ọ lọ lati bere lọwọ rẹ̀ boya on faramọ hihuwa ti o huwa pẹlu imọtara-ẹni-nikan lori ọran na tabi bẹkọ. On iba ti tako itanjẹ na. Ṣugbọn Efa yọnda ara rẹ̀ lati di ẹniti a tanjẹ daradara. On gbọjẹgẹ fun ero buburu ti eleke na mu wa sọdọ rẹ̀, abanijẹ ati alatako Ọlọrun Baba rẹ̀ ọrun. On jẹ ki ibẹru fun ijiya bibanilẹru fun aigbọran na fo lọ. O jẹ ki ifẹ imọti-ara-ẹni nikan bẹrẹ si dagba ninu ọkan rẹ̀. O jẹ ki ifẹkufẹ yi fà a lọ ki a si tan a jẹ. Ọlọrun ti sọ pe yio buru fun u ati Adamu lati jẹ ninu eso igi ti a kàléwò na, ṣugbọn on pinnu lati gbekalẹ fun ara rẹ̀ ohun ti o buru ati ohun ti o dara. Bẹ gẹgẹ on pinnu lati mu Ọlọrun ati Baba rẹ̀ ọrun li eleke. Nitorina nisisiyi nigbati Efa bẹrẹ si ronu nipa igi na, o bẹrẹ si dara ni wiwo.

12. Nipa jijẹ eso ti a kàléwò na, kini Efa dà, laisi awawi kankan?

12 “Nigbati obirin na si rii, igi na dara ni jijẹ, ati pe, o si dara fun oju, ati igi ti a ifẹ lati mu ni gbọn, o mu ninu eso rẹ̀ o si jẹ.” (Genesisi 3:6) Li ọna bayi on di olurekọja si Ọlọrun, ẹlẹṣẹ. Otitọ na pe a tan a jẹ daradara ko dá a lare. O padanu ijẹpipe iwarere rẹ̀.

13. Nipa jijẹ ẹ, kini Adamu kuna lati ṣe, pẹlu iyọrisi wo li ori rẹ̀?

13 Ọkọ rẹ̀ ko si nibẹ lati ṣe idiwọ fun iwa ominira rẹ̀. Nigbati on wa darapọ mọ ọ, on nilati lo iyinilọkanpada lati mu ki o jẹ ẹ, nitori pe a ko tan an jẹ lọnakọna. On ko yan lati fi ẹniti nsọrọ nipasẹ ejo na han li eleke ki o si da Jehofah Ọlọrun lare gẹgẹ bi Ẹniti nlo jijẹ ọba alaṣẹ agbaiye Rẹ̀ li ọna ododo, ọna ti o ṣanfani. Nigbana, kini ṣẹlẹ nigbati Adamu darapọ mọ Efa ninu irekọja? Genesisi 3:6, 7 sọ fun wa:

“O si fi fun ọkọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, on si jẹ. Oju awọn mejeji si la, nwọn si mọ pe nwọn wa ni ihoho; nwọn si gan ewe ọpọtọ pọ, nwọn si dá ibantẹ fun ara wọn”.

14. Kini sún Adamu ati Efa lati dá ara wọn lẹbi ki Ọlọrun to ṣe bẹ, bawo ni nwọn si ti ṣe huwa nigbati o mbọ?

14 Nwọn ti wa “dabi Ọlọrun nisisiyi, nwọn si ti “ímọ rere ati buburu,” niti pe nwọn ko tun tẹwọgba awọn ilana fun rere ati buburu gẹgẹ bi Jehofah Ọlọrun ti fi lẹlẹ ṣugbọn nwọn ti di awọn onidajọ fun ara wọn nipa ohun ti o buru ati ohun ti o dara. Laika eyi si, ẹri ọkan wọn bẹrẹ si dẹrupa wọn. Nwọn dabi ẹniti a tú si ihoho, ti o nfẹ ibora. Ihoho ara wọn ki itun ṣe ipo mimọ, alailẹṣẹ loju ara wọn mọ, ninu eyiti nwọn yio farahan niwaju Jehofah Ọlọrun. Nitorina nwọn bẹrẹ si ran aṣọ nwọn si bo ibi ikọkọ wọn ti Ọlọrun ti fi fun wọn fun ete ọlọla ti mimu irú wọn jade. Nipa bayi, labẹ ẹri-ọkan wọn funrawọn ti nda wọn lẹbi, nwọn da ara wọn lẹbi, ani ṣaju ki Jehofah Oluwa Ọba Alaṣẹ to ṣe bẹ, Nipa bayi, a kà pe:

“Nwọn si gbọ ohùn [Jehofah] Ọlọrun, o nrin ninu ọgba ni itura ọjọ: Adamu ati aya rẹ̀ si fi ara wọn pamọ kuro niwaju [Jehofah] Ọlọrun larin igi ọgba. [Jehofah] Ọlọrun si kọ si Adamu, o si wi fun u pe, Nibo ni iwọ wà? O si wipe, ‘Mo gbọ ohùn rẹ ninu ọgba, ẹ̀rù si bà mi, nitori ti mo wà ni ihoho; mo si fi ara pamọ,’ O si wipe, Tali o wi fun ọ pe iwọ wa ni ihoho? Iwọ ha jẹ ninu igi nì, ninu eyiti mo paṣẹ fun ọ pe iwọ ko gbọdọ jẹ?’”—Genesisi 3:8-11.

15. (a) Kini fihan pe ko si ironupiwada lọdọ Adamu ati Efa? (b) Kini Ọlọrun sọ fun ejo na nigbana?

15 Jẹ ki a ṣakiyesi, nisisiyi, pe ko si ọrọ ironupiwada kankan lati ọdọ Adamu ati Efa wa, ṣugbọn, kakabẹ, isapa lati dare fun ara wọn: Ẹlomiran li a nilati dẹbi fun. “Ọkunrin na si wipe, Obirin ti iwọ fi pẹlu mi, on li o fun mi ninu eso igi na, emi si jẹ. [Jehofah] Ọlọrun si bi obirin na pe, Ewo ni iwọ ṣe yi? Obirin na si wipe, Ejo li o tan mi, mo si jẹ.” Biotiwukiori, awawi ko da awọn ti o mọmọ rekọja wọnyì lare. Ṣugbọn niti ejo nkọ?

‘’[Jehofah] si wi fun ejo na pe, nitori ti iwọ ti ṣe eyi, a fi iwọ bú ninu gbogbo ẹran ati ninu gbogbo ẹranko igbẹ; inu rẹ ni iwọ o fi ma wọ, ẹrupẹ ilẹ ni iwọ o má jẹ li ọjọ aiye rẹ gbogbo. Emi o si fi ọta sarin iwọ ati obirin na, ati sarin iru ọmọ rẹ ati iru-ọmọ rẹ̀: on o fọ ọ li ori, iwọ o si pa a ni gigisẹ.“—Genesisi 3:14, 15, NW); Leeser; Zunz.

16, 17. (a) Tani awọn ọrọ Ọlọrun si ejo na kàn nitoôtọ? (b) Kini akọwe kan ni ọgọrun ọdun ekini fi irẹsilẹ yi we?

16 Eyiyi ki iṣe gún lori gbogbo idile ejo. O dabi ẹni pe awọn ọrọ Ọlọrun li a dari rẹ̀ si ejo gidi na, ṣugbọn On mọ̀ pe a wulẹ rẹ̀ ẹ jẹ lasan ni lati ṣiṣẹ gẹgẹ bi ohun elo lati ọwọ ẹda ẹmi kan ti a ko le fojuri ti o lagbara ju enia, ọ̀kan ti o ti jẹ ọmọ Ọlọrun onigbọran li ọrun tẹlẹri. Eyiyi pẹlu si ti gba ki a fa on lọ ti o si jẹ ki iru onimọ-ti-ara-ẹni nikan bẹ tan on jẹ. O jẹ ifẹ kan fun ipo ọba alaṣẹ lori araiye, laini nkankan iṣe pẹlu ipo ọba alaṣẹ agbaiye ti Jehofah. Ifẹ yi li o ti jẹki o ta gbongbo ninu ọkan rẹ̀ o si ti mu u dagba, titi o fi loyun ti o si bi ẹṣẹ, iṣọtẹ lodi si Jehofah Oluwa Ọba Alaṣẹ. Nigbana ni ẹmi ẹlẹṣẹ na sọ ara rẹ̀ di eke, abanijẹ tabi Eṣu ati alatako tabi Satani, nibẹ gan ninu Paradise Igbadun.

17 Gẹgẹ bi a ti sọ funni nipa irẹsilẹ ti a kede sori ejo na ti a rẹ̀jẹ, Ọlọrun rẹ̀ Satani, Eṣu, Eleke titun ti o ṣẹṣẹ dide yi silẹ. Alasọye kan lori Bibeli ni ọgọrun ọdun ekini fi irẹsilẹ yi we ’jiju Satani sinu Tartaru,’ ipo aini-itẹwọgba ti okunkun nipa ti ẹmi laisi ilaloye kankan lati ọdọ Ọlọrun.—2 Peteru 2:4.

A SỌ ẸNI AMI ORORO ỌLỌRUN TẸLẸ

18. Kini ohun titun kan ti a kede rẹ̀ nihinyi, pẹlu awọn ami wo nipa rẹ̀?

18 Nihin ni Jehofah Ọlọrun gbe ete titun kan kalẹ, o si kede rẹ̀. Satani Eṣu eleke na ti dide, o si wa di ete Ọlọrun nisisiyi lati gbe Ẹni Ami Ororo Kan, Ma-shi’ahh, (Messiah) kan dide gẹgẹ bi ede Adamu ti wi. (Danieli 9:25) Ọlọrun yio fi ọta sarin Ẹni Ami Ororo yi ati Satani Eṣu, ẹniti ejo na ṣapẹrẹ rẹ̀ nisisiyi. Ọta yi pẹlu yio mu ara rẹ̀ gbérò de wiwà larin Ẹni Ami Ororo na ati “iru-ọmọ” Ejo Nla na.

19. (a) Ninu ija wo ni “ọta” yi nilati yọrisi? (b) Eṣe ti Ẹni Ami Ororo ti ete Jehofah fi nilati jẹ ti ọrun?

19 Ọta ti a sọtẹlẹ na nilati yọrisi ogun kan ti yio ni awọn iyọrisi kikoro, ṣugbọn yio dopin pẹlu iṣẹgun fun “iru-ọmọ!” ’’obirin na.” Gẹgẹ bi ejo kan ti o bù gigisẹ jẹ (Genesisi 49:17), Ejo Nla ná, Satani Eṣu, yio dá ọgbẹ si gigisẹ “iru-ọmọ?” obirin na. Ọgbẹ gigisẹ yi ko ni mu iku lọwọ. A wò o san, lati mu ki o ṣéṣe fun “iru-ọmọ” obirin na lati fọ Ejo Nla na li ori li apaku. Nipa bayi Ejo Nla na yio parun, ati “iru-ọmọ” rẹ̀ pẹlu rẹ̀. Ohun pataki kan ti a nilati fi sọkan nipa ijakadi yi ni yi: Fun “iru-ọmọ” obirin na lati fọ ati lati run ori Ejo Nla na wòmú- wòmú, Satani Eṣu, ’iru-ọmọ!” obirin nilati jẹ ẹda ẹmi li ọrun, ki iṣe enia kan lasan ti o jẹ ọmọ obirin kan li aiye. Eṣe ti o fi jẹ bẹ? Nitoripe Ejo Nla na jẹ ẹda ẹmi ti o lagbara ju enia lọ, ọlọtẹ ọmọ Ọlọrun kan li ọrun. “Iru-ọmọ’’ enia kan lasan ti o jẹ ti obirin kan li aiye ko ni lagbara to lati pa Satani Eṣu na run, ẹniti a ko le fojuri ninu ilẹ ọba ẹmi. Nitorina Ẹni Ami Ororo na ti o jẹ ti ete Jehofah nilati jẹ Messiah kan li ọrun.

20. Nigbana, tani “obirin”? inu Genesisi 3:15 na?

20 O dara, nigbana, bawo ni ti “obirin” na ẹniti iru-ọmọ!” rẹ̀ Ẹni Ami Ororo na tabi Messiah iṣe? On, pẹlu, nilati jẹ ti ọrun. Gán gẹgẹ bi ejo na ti a lo lati tan Efa jẹ, bẹ gẹgẹ ni “obirin” na ninu asọtẹlẹ Jehofah ninu Genesisi 3:15 ki iṣe obirin gidi kan li aiye. Efa jẹ ẹlẹṣẹ funrarẹ̀ lodi si ofin Ọlọrun on li o si fa ọkọ rẹ̀ Adamu sinu ẹṣẹ. Nitorina on funrarẹ̀ ko yẹ fun jíjẹ ìyá táràtà fun “iru-ọmọ” ti a ṣeleri na. ‘’Obirin’’ asọtẹlẹ Ọlọrun nilati jẹ obirin iṣapẹrẹ. Ṣe li o dabi igbati Jehofah Ọlọrun sọrọ nipa awọn enia ayanfẹ gẹgẹ bi aya rẹ̀, obirin rẹ̀, ti o nwi fun wọn pe: Pada, ẹnyin apẹhinda ọmọ, li Oluwa wi, nitori emi gbe nyin ni iyawo.” (Jeremiah 3:14; 31:31, Leeser [31:32, NW]) Bẹ gẹgẹ eto Ọlọrun li ọrun ti o jẹ ti awọn angeli mimọ dabi iyawo fun Jehofah Ọlọrun, on si jẹ iya ti ọrun fun “iru-ọmọ” na. On li “obirin na’’ Arin “obirin” yi ati Ejo na li Ọlọrun fi ọta si.

ETE AKỌKỌBẸRẸ KO NILATI JẸ IKUNA KAN

21. Ete Ọlọrun ni ijimiji nipa ilẹ aiye nisisiyi ha nilati kuna nitori irekọja ti o ṣẹlẹ?

21 Kini, nigbana, nipa ete Ọlọrun nipa ilẹ aiye gẹgẹ bi a ti sọ ọ fun Adamu ati Efa ni opin “ọjọ” iṣẹda kẹfa? O ha nilati kuna nisisiyi nitori ẹṣẹ Efa ati Adamu, eyiti o fa fifi iku pa wọn? Ete akọkọbẹrẹ yi ni lati sọ gbogbo ilẹ aiye di Paradise kan, ki o kun fun awọn enia atọmọdọmọ ọkunrin ati obirin ekini, akọkọ, Adamu ati Efa. Ikuna li ohun kan ti ko le ṣẹlẹ si ete Ọlọrun ti a kede. Ko si Satani Eṣu Kankan ti o le mu ki ete Ọlọrun kuna ki o si dojuti i. Pe ete Ọlọrun ní ibẹrẹ nilati tẹsiwaju si imuṣẹ iṣẹgun li a fihan ninu ohun ti a wi nisisiyi si obirin na Efa lati ọdọ Jehofah Ọlọrun Onidajọ Gigajulọ.

22. (a) Fifi enia kún orilẹ aiye nipasẹ tani ni yio má ba a lọ? (b) O ha lọgbọn ninu lati gbagbọ pe fifọ ori Ejo na nilati yọrisi anfani fun araiye?

22 Fun obirin na li o wipe, Emi o sọ ipọnju ati iloyun rẹ di pupọ; ni ipọnju ni iwọ o má bimọ; lọdọ ọkọ rẹ ni ifẹ rẹ yio ma fà si, on ni yio si má ṣe olori rẹ,” (Genesisi 3:16) Eyiyi fihan pe mimu awọn olugbe ilẹ aiye jade siwaju si i lati ọdọ tọkọtaya enia akọkọ yì li a nilati yọda fun. O ti mba a lọ titi di isisiyi, loni ọrọ ti ndanilamu si mbẹ nipa “akunya iye enia.” Niwọnbi Ejo Nla na, Satani Eṣu, ti ṣe okunfa mimu iku wá sori gbogbo atọmọdọmọ tọkọtaya enia akọkọ, dajudaju fifọ “ori” Ejo Nla yi nilati yọrisi anfani fun awọn atọmọdọmọ wọnni ti ẹṣẹ rẹ̀ ti palara. Ni pataki bawo? Eyini jẹ ohun kan fun Jehofah Ọlọrun lati mu ṣe kedere laipẹ. Eyiyi yio ṣe iṣẹ fun iyọrisi rere ete Rẹ̀ akọkọbẹrẹ.

23-25. (a) Nigbawo ni a kede idajọ iku le Adamu lori fun irekọja rẹ̀? (b) Li ọna wo, nigbana, li o fi jẹ pe Adamu kú li ọjọ na ti on jẹ eso na ti a kà léwọ, nipa ti awọn ọmọ rẹ̀ nkọ?

23 Nisisiyi, lakotan, o yí kàn ọkunrin na, ẹni kẹta ninu itolẹṣẹṣẹ ẹṣẹ dida. Ọlọrun ti sọ fun u pe li ọjọ ti o ba jẹ ninu eso ti a kaléwọ̀ na, ni yio ku. (Genesisi 2:17) Fun aya rẹ̀ Efa lati mu awọn ọmọ jade ninu irora ibimọ, yio bere pe ki Adamu waláye titi gẹgẹbi ọkọ rẹ̀ ki o si di baba awọn ọmọ rẹ̀. Nitorina bawo ni a ti ṣe aṣeyọri ohun ti Ọlọrun kilọ fun u nipa rẹ̀?

24Genesisi 3:17-19 fihan kedere bawo ni: “O si wi fun Adamu pe, Nitoriti iwọ gba ohùn aya rẹ gbọ, ti iwọ si jẹ ninu eso igi na, ninu eyiti mo ti paṣẹ fun ọ pe, iwọ ko gbọdọ jẹ ninu rẹ̀, a fi ilẹ bú nitori rẹ; ni ipọnju ni iwọ o ma jẹ ninu rẹ̀ li ọjọ aiye rẹ gbogbo; ẹ̀gún on oṣuṣu ni yio má hù jade fun ọ, iwọ o si má jẹ eweko igbẹ. Li ôgùn oju rẹ ni iwọ o ma jẹun, titi ìwọ o fi pada si ilẹ; nitori inu rẹ̀ li a ti mu ọ wá, erupẹ sa ni iwọ, ìwọ o si pada di erupẹ.” Pẹlu awọn ọrọ idajọ wọnni, Jehofah Ọlọrun kede idajọ iku sori ẹlẹṣẹ na, eyiyi si jẹ larin ọjọ kanna ninu eyiti Adamu ti dẹṣẹ.

25 Lọna idajọ, niha ọdọ Ọlọrun, Adamu kú li ọjọ na gán, Efa iyawo rẹ̀ ẹlẹṣẹ na si kú pẹlu. Ohun ti a ké kuro lọdọ awọn mejeji ni anfani ati ireti wiwaláye titilai ninu ayọ ninu Paradise Igbadun na. On ku nisisiyi ninu irekọja rẹ̀. Lati igbana ohun ti on le nasẹ rẹ̀ de ọdọ awọn ọmọ rẹ̀ nipasẹ Efa ni kiki iwaláye ti nmu iku dani ati idalẹbi, nitori aipe enia ti a jogun. Gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ yio nilati wipe, gẹgẹbi Dafidi onipsalmu na ti wi ni ẹgbẹgbẹrun ọdun sẹhin: “Kiyesi i, ninu aiṣedédé li a gbe bi mi: Ati ninu ẹṣẹ ni iya mi si loyun mi.” (Orin Dafidi 51:5) Fun gbogbo araiye ẹlẹṣẹ li Ọlọrun le wi, gẹgẹbi o ti wi fun awọn enia ayanfẹ rẹ̀ pe: “Baba rẹ iṣaju ti ṣẹ̀.” (Isaiah 43:27) Gbogbo araiye ku ninu Adamu li ọjọ na ti Onidajọ Gigajulọ kede idajọ le e lori fun ẹṣẹ rẹ̀. Lẹhinti Adamu ti gba idajọ rẹ̀ tan, iku nipa ti ara ko ṣe yẹsilẹ fun u mọ.

26. Ani nigbati a ba tilẹ fi oju wo “ọjọ” kan bi ẹgbẹrun ọdun, bawo ni Adamu ṣe ku li ọjọ irekọja rẹ̀, kini on si ṣiwọ lati jẹ?

26 Pẹlu iṣedédé, “iwe [itan] Adamu” sọ fun wa pe ‘’O si bí ọmọkunrin ati ọmọbirin: gbogbo ọjọ ti Adamu wà si jẹ ẹdẹgbẹrun ọdun o le ọgbọn: o si ku.” (Genesisi 5:1-5) O gbe li aye li ẹgbẹrun ọdun din adọrun ọdun. Ko si ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀ ti o tí gbe aiye li ẹgbẹrun ọdun ri ni kikun, ọkan ti o darugbo julọ, Metuselah, gbe aiye li ẹgbẹrun ọdun o din mọkanlelọgbọn. (Genesisi 5:27) Ani niti oju ti Ọlọrun fi wo ẹgbẹrun ọdun gẹgẹ bi ọjọ kan, Adamu ku larin “ọjọ” ẹlẹgbẹrun ọdun ekini ninu iwaláye enia. Nibo li on lọ nigba iku rẹ̀ nipa ti ara? A ko tilẹ mu “ọkàn”(neph’esh) rẹ̀ wá lati ọrun, on ko si “pada” si ibẹ. O pada nitotọ si erupẹ ilẹ, nitoripe, gẹgẹ bi Ọlọrun ti wi, lati ibẹ li a ti mu Adamu wá. Nigbana li o dẹkun lati jẹ “aláyé ọkàn.” (Genesisi 2:7) O ṣiwọ lati waláye. Nigbati Efa aya rẹ̀ ku iku ti ara, on, pẹlu, ṣiwọ lati jẹ “aláyé ọkàn” kan. Ko si ọkàn kankan lati má waláye niṣo titi lai gẹgẹbi itan arosọ isin Babiloni ti wì.

IPADANU PARADISE

27. Apa wo lori ilẹ aiye ni fifi ilẹ gegun kàn, ki si ni ṣiṣe iṣẹ ti Adamu nṣe iṣẹ lori ilẹ ti a fi gegun tumọsi fun on ati Efa?

27 Ọrọ idajọ Ọlọrun sori Adamu, ni pataki awọn ọrọ nipa “ilẹ ... ti a fi bú,” tumọsi pe Adamu nilati padanu Paradise. O padanu rẹ̀ nitôtọ. A ko gegun fun Paradise nitori irekọja Efa ati Adamu; o mba a lọ lati jẹ ibi iwaláyé kan, ti o ṣi ní ninu rẹ̀ “igi iye” na. Genesisi 3:20-24 sọ fun wa pe:

Adamu si pe orukọ aya rẹ̀ ni Efa; nitori on ni iṣe iya aláyé gbogbo. Ati fun Adamu ati fun aya rẹ̀ ni [Jehofah] Ọlọrun da ẹwu awọ, o si fi wọ wọn.[Jehofah] Ọlọrun si wipe, Wo o, Ọkunrin na dabi ọkan ninu wa lati mọ rere ati buburu: njẹ nisisiyi ki o má ba na ọwọ rẹ̀ ki o si mu ninu eso igi iye pẹlu, ki o si jẹ, ki o si yò titi lai. Nitorina [Jehofah] Ọlọrun lé e jade kuro ninu ọgba Edeni, lati ma ro ilẹ ninu eyiti a ti mu u jade wa. Bẹli o lé ọkunrin na jade; o si fi awọn kerubu de iha ila-orun Edeni ati ida ina ti nju kakiri, lati má ṣọ ọna igi iye na.”

28. Eṣe ti iye titilai ko tun fi ṣéṣe fun Adamu?

28 Nitori nini agbara iku, Jehofah Ọlọrun mu ọkunrin na jinna si igi iye na, ki o ba le mu ijiya iku na lagbara lori Adamu. Aya Adamu tẹle ọkọ rẹ̀ ki o ba le di iya fun awọn ọmọ rẹ̀. Boya Ọlọrun le ejo na jade eyiti a lo lati fi tan Efa jẹ, akọsilẹ na ko fihan. Iwaláye titi lai ko tun ṣéṣe fun Adamu ati Efa.

29. (a) Bawo ni Ọlọrun ṣe fi ’ọta” sarin “obirin”? na ati “ejo” na? (b) Iyọrisi wo ni ikede ete Ọlọrun ní lori ete rẹ̀ akọkọ fun ilẹ aiye, esitiṣe ti awa fi le layọ nisisiyi?

29 Ko si akọsilẹ pe, lẹhin ode ọgba Edeni, Efa mu awọn ọmọ rẹ̀ jade lati korira awọn ejo. Ṣugbọn eto Ọlọrun li ọrun ti awọn angeli mimọ, ’’obirin” tôtọ na, ti a sọrọ rẹ̀ ninu Genesisi 3:15 ninu asọtẹlẹ lọrun, bẹrẹsi korira Ejo Nla na, Satani Eṣu. Ifẹ fun Jehofah Ọlọrun gẹgẹbi ọkọ rẹ̀ ọrun sún eto ti o dabi aya na lati ṣe bẹ. Nitôtọ Ọlọrun fi ọta sarin ’obirin” Rẹ̀ ati Ejo Nla na. Igbati on yio mu “iru-ọmọ” na jade eyiti yio fọ ori Ejo Nla na, wà ninu ete Jehofah Ọlọrun. Nisisiyi o ti gbe ete rẹ̀ kalẹ ninu Ẹni Ami Ororo rẹ̀, Messiah rẹ̀, o si ti mu ki otitọ na di mimọ fun ọrun on aiye, nisisiyi ni nkan bi ẹgbata ọdun sẹhin. Eyini jẹ awọn sanmani akoko sẹhin. Afikun ete yi fi agbara kún ete Ọlọrun li akọkọ nipa Paradise ilẹ aiye kan o si mu imuṣẹ rẹ̀ daju. Ọlọrun ti ki yipada na ṣi rọmọ ete na ti a kede ninu Ẹni Ami Ororo rẹ̀, Messiah rẹ̀. Awa le layọ gidigidi pe o ti nṣẹgun nissiyi fun ire enia.

[Ibeere]