Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Awa Wà ninu Ete Ẹlẹda Onifẹ

Awa Wà ninu Ete Ẹlẹda Onifẹ

ORI 1

Awa Wà ninu Ete Ẹlẹda Onifẹ

1, 2. Eṣe ti iye awọn enia ti npọ si i fi nní ifẹ akọtun si iwalayè lori ilẹ aiye?

BI ỌGỌRUN ọdun lọna ogún wa yi ti nsunmọ opin rẹ̀, iye awọn enia ti o tubọ npọ si i nni ifẹ akọtun ninu ireti fun wiwà láyè lori ilẹ aiye.

2Eto awọn nkan ti nkú lọ labẹ eyiti a nri i pe o ṣoro siwaju ati siwaju lati gbe ki iṣe ohun ti o kẹhin fun wa lati ní iriri rẹ̀. Ki iṣe gbogbo ohun ti o wà nibẹ fun wa li eyini. Ilẹ aiye yio dẹkun lati jẹ ibi kan fun ijiya enia lati igba de igba. Okunkun biribiri ti o bò gbogbo aiye mọlẹ pẹlu ìṣúdùdù ti o le mu iku wá ti fẹrẹ kásẹ̀ nilẹ. Dajudaju ọjọ titun ti yio tẹle òru na ti fẹrẹ de fun gbogbo aiye lati di ibikan fun igbesi aiye alayọ fun gbogbo idile aiye. Gbogbo eyi ki iṣe ohun akọsẹba kan, ki iṣe ọran éeṣì, ki tilẹ iṣe ọran aṣeyọri ọgbọn ijinlẹ enia kan. Ẹnikan ti o ga ju enia lọ li o pete rẹ̀.

3. Bawo ni ero titun lori iye lori ilẹ aiye ṣe kan awọn onisin Budha, Hindu ati awọn onigbagbọ ninu Ayanmọ?

3 Bẹni, iye oniruru awọn enia ti npọ si i li o nharagàgà pẹlu ayọ bi nwọn ti nfojusọna fun iye lori ilẹ aiye wa ogbologbo kanna, ṣugbọn labẹ eto awọn nkan titun ti nfunni-ni-iye. Lara awọn wọnyi ni onisin Budha kan ti o ti fi igba kan ri nká awọn ọwọ rẹ̀ kò ti o si ngbadura niwaju ere ọlọrun rẹ̀ oniwura ti o nṣe aṣaro ti o si ti ri idi titun nisisiyi fun gbigbadun iwàláyé enia lori ilẹ aiye nisisiyi ati titilai. Onisin Hindu nigbakanri ti o ti saba ma njọsin niwaju Trimurti ọlọrun mẹtalọkan rẹ̀ ko tun gbiyanju lati gbe ọlá kalẹ fun ara rẹ̀ labẹ ẹ̀rù ironu pe ọkàn enia nṣipo-pada lẹhin iku. Pẹlu ire onifẹ fun gbogbo araiye iran on nṣe awari kiri nisisiyi lati ṣe ajọpin pẹlu awọn ẹlomiran ihinrere na pe idile enia yio wọ inu iye ti o daraju lori ilẹ aiye nihin. Onisin na ti o ti gbagbọ nigbakanri pe gbogbo ọran on ni Qadar (“Ayanmọ”) nṣakoso rẹ̀ nisisiyi nfẹ lati jẹ ẹni yiyẹ lati gbadun paradise kan nihin lori ilẹ aiye, eyiti o lẹwa ju Damasku igbani páapáa.

4. Bawo ni awọn onisin Kristendom ṣe yi ireti wọn pada?

4 Roman Katholik, tabi Griki Orthodox, tabi Protestant na nigbakanri, ti o nfojusọna lati di angeli kan li ọrun dipo ki o jó àjórun titilai ninu ina ọrun apádì kan ati sulfuru, nmura ara rẹ̀ silẹ nisisiyi fun iye ailopin ninu ijẹpipe enia lori ilẹ aiye alalafia ati alábò.

5. Bawo ni o ṣe kan awọn alaifẹran isin bakanna?

5 Wo awọn iyipada lọna isin ti gbogbo eyini jẹ! Ṣugbọn iru awọn iyipada bawọnni li a ko fimọ sọdọ awọn enia onisin olotọ ọkàn nikan. Ani awọn enia ti ki iṣe onisin ti ni iriri iyipada ero lori iye lori ilẹ aiye yi. Ẹlẹkọ efolusion nigbakanri, ti o ti làkàkà lati mu igbagbọ nlanla jade lati gbagbọ pe iwaláyè enia ṣeṣi bẹrẹ lati inu ohun bintin kan ni ijimiji lati inu okun, alailẹmi-gigun, ti o si fi tagbara-tagbara dagba di iwaláyè enia isisiyi, ko tun gbarale iyipada ati ọgbọn ijinlẹ ode oni nipa ohun ti on yio dà li ọjọ ọla. Kommunist “alailọlọrun” nigbakanri kan, ti o Pg6gba ohun ti a fojuri nikan gbọ ti o si nṣiṣẹ fun sisọ gbogbo aiye di kommunist labẹ eto iṣelu ijọba alaifẹran isin, nisisiyi ni ireti fun iṣakoso agbaiye kan ti o gaju ti awọn ẹda ti nku, alaipe, onimọ-ti-ara-nikan ati ẹlẹjẹ̀ ati ẹlẹran ara.

6. Ni ibamu pẹlu kini li awọn wọnni nyi igbesi aiye wọn pada nisisiyi?

6 Gbogbo awọn ti a yipada wọnyi, onisin ati alaifẹran isin nfojusọna fun iye lori ilẹ aiye pẹlu idaniloju lati di ẹniti o daraju ninu iran tiwọn funrawọn. Nisisiyi nwọn nmu igbesi aiye wọn dọgba pẹlu ireti awọn nkan ologo ti a mu daniloju lati wà fun awọn olugbe aiye. Igbesi aiye wọn isisiyi layọ ju fun eyi, o wulo ju, o ṣanfani ju fun wọn ati awọn ẹlomiran. Pẹlu iṣọkan, gbogbo wọn li o ni ireti yi papọ fun awọn ọdun ti mbọ. Kini mu iyipada agbayanu yi wá ninu iye-inu ati ọkàn ati igbesi aiye wọn?

7. Kini mu iyipada yi wá ninu iru awọn enia bẹ?

7 Eyi ni: Nwọn ti wá sinu imọ pipe perepere ti “ete aiyeraiye” Ọlọrun nwọn si nmu igbesi aiye wọn wà ni ibamu pẹlu ete atọrunwa na, nwọn nyọ ninu ọkàn wọn nitoripe o nṣẹgun nisisiyi fun ire ainipẹkun fun gbogbo araiye. Nwọn fi tirẹlẹ-tirẹlẹ dupẹ pe awọn na, pẹlu, wà ninu ete Ọlọrun Ẹlẹda wọn onifẹ. Gbigbe ninu álà ete Rẹ̀ mu ki igbesi aiye ní itumọ fun wọn. Ayọ aiyeraiye mbẹ niwaju wọn.

[Ibeere]