Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹgun fun “Ete Aiyeraiye” Na

Iṣẹgun fun “Ete Aiyeraiye” Na

Ori 14

Iṣẹgun fun “Ete Aiyeraiye” Na

1. Awọn wo li o ti jẹ alatako “ete aiyeraiye” Ọlọrun ti ẹmi, lati igbawo si ni?

“ETE AIYERAIYE!” Ọlọrun ní awọn alatako rẹ̀ li ọrun ati li aiye. Nwọn ti jà nwọn si tun njà lọwọ lati ṣe idiwọ fun iṣẹgun patapata fun “ete aiyeraiye” na. Nigbati Ọlọrun kede “ete aiyeraiye” rẹ̀ ni Ọgba Edeni li etigbọ Ejo Nla na ati ti Adamu ati Efa ẹlẹṣẹ, Ọlọrun wi fun Ejo na pe: “Emi o si fi ọta sarin iwọ ati obirin na, ati sarin iru-ọmọ rẹ ati iru-ọmọ rẹ̀: on o fọ ọ li ori, iwọ o si pa a ni gigisẹ.” (Genesisi 3:15) Lati igbana ni Satani Eṣu ati awọn alaigbọran angeli wọnni ti nwọn ti di ẹmi eṣu ti fi pẹlu isowọpọ ba ete Ọlọrun ti a kede na jà.

2. (a) Nipasẹ awọn ọna wo li awọn igbiyanju ẹlẹmi eṣu fi wa lati pa “iran” titun “ti a yan” ti a ṣẹṣẹ dá silẹ na run? (b) Kini Peteru kọwe rẹ̀ ni kikilọ nipa ikọlu awọn enia oniwa ibajẹ?

2 Lẹhinti a dá “Israeli Ọlọrun” ti ẹmi silẹ lori awọn ipilẹ aposteli mejila rẹ̀ li ọjọ ajọdun Pentikosti ti 33 C.E., awọn igbiyanju ẹlẹmi eṣu mbẹ lori ilẹ aiye lati pa “iran” titun “ti a yan” yi, “olu alufa” yi, “orilẹ-ede mimọ” yi run. (1 Peteru 2:9) Lakọkọ, a lo inunibini oniwa-ipa, ṣugbọn eyi kuna, (Iṣe 7:59 titi de 8:4; 9:1-5, 21; 11:19) Nigbana a ṣe igbiyanju biba Israeli ti ẹmì jẹ ninu awọn ẹkọ rẹ̀ ati ọna igbesi aiye, o si ṣe ipalara nlanla. Aposteli Peteru, nigbati o nkọwe si awọn ti o di igbagbọ Kristian mu ni nkan bi ọdun 64 C.E., kilọ fun awọn Kristian ọgọrun ọdun ekini tẹlẹ nipa wiwọle-wa ibajẹ nipa ti ẹmi yi wipe:

“Nitori asọtẹlẹ kan ko ti ipa ifẹ enia wa ri; ṣugbọn awọn enia nsọrọ lati ọdọ Ọlọrun bi a ti ndari wọn lati ọwọ ẹmi mimọ wa. Ṣugbọn, awọn woli eke wà larin awọn enia na pẹlu, gẹgẹ bi awọn olukọni eke yio ti wà larin nyin, awọn ẹniti yio yọ mu adamọ ẹ̀gbé wọ inu nyin wa, ani ti yio ṣẹ̀ Oluwa ti o rà wọn, nwọn o si mu iparun ti o yara kánkán wá gori ara wọn. Ọpọlọpọ ni yio si má, tẹle iwa wọbia wọn ; nipa awọn ẹniti ao fi ma sọ ọrọ-odi si ọna otitọ. Ati ninu ojukokoro ni nwọn o má fi nyin ṣe èrè jẹ nipa ọrọ ẹtan: idajọ ẹniti ko falẹ lati ọjọ iwa, iparun wọn ko si togbe.” —2 Peteru 1:21 titi de 2:3; wo Juda 4 pẹlu.

3. (a) Bawo ni Paulu ṣe kilọ nipa awọn oluba-ijọ-jẹ? (b) Tani “ẹni ẹṣẹ nì,” nigbawo li ẹni yi si fi ara han?

3 Bẹ gẹgẹ, aposteli Paulu, nigbati o nṣe irin-ajo ikẹhin rẹ̀ lọ si Jerusalemu, kilọ fun awọn alagba ijọ Kristian: “Emi mọ pe, lẹhin lilọ mi, ikôkò buburu yio wọ árin nyin, li aida agbo si. Ati larin ẹnyin tikaranyin li awọn enia yio dide, ti nwọn o má sọrọ òdì, lati fa awọn ọmọ-ẹhin sẹhin wọn.” (Iṣẹ 20’:29, 30) Pẹlu-pẹlu, ninu lẹta kan ti o kọ si ijọ Tessalonika ṣaju ni Makedonia, o ṣe ikilọ kan nipa bibẹsilẹ iṣọtẹ nipa isin ninu ijọ ati fifi “ẹni ẹṣẹ nì” han, “ọmọ egbe.” Paulu kilọ pe “ẹnikan wà ti nṣe idena nisisiyi.” “Ẹmi ẹṣẹ” na nilati jẹ apapọ enia, awọn alufa Kristendom. (2 Tessalonika 2:3-9) Apapọ “ẹni ẹṣẹ” yi li a fihan ni ọgọrun ọdun kẹrin Sanmani Tiwa, nigbati ọba nla Romu, Constantine Nla, ba awọn oniwa ibajẹ “biṣọpu” lo ti o si sọ isin wọn di ti ijọba ilu fun Ilẹ Ọba Romu. Constantine gbe oyè alufa kalẹ. Nipa bayi Kristendom bẹrẹ.

4. Nigba ọgọrọrun ọdun lati igba idasilẹ rẹ̀, akọsilẹ wo li awọn alufa Kristendom ti ṣe fun ara wọn, sibẹ kini Kristendom sọ pe on jẹ?

4 Fun ọgọrun ọdun mẹrindinlogun ti o tẹle e, titi de ọgọrun ọdun lọna ogun yi, iru akọsilẹ wo ni Kristendom ti ṣe fun ara rẹ̀? Akọsilẹ awọn alufa rẹ̀ ti o nlọwọ si iṣelu, ti o nmu awọn ẹkọ abọriṣa jade siwaju ati siwaju fun igbagbọ isin wọn, kiko ọrọ̀ ati agbara jọ fun ara wọn, ti nwọn npọ́n awọn agbo isin wọn loju, ti nwọn ndá ogun isin silẹ, awọn ogun isin oníkà ati inunibini, ti nwọn ngbe ọgọrọrun awọn ẹya isin idarudapọ kalẹ, ti nwọn nbukun awọn ọmọ ogun awọn ẹniti a fi ẹnu lasan pe ni awọn orilẹ-ede “Kristian” ti o mba ara wọn jagun, ti nwọn mba iwarere awọn ọmọ ijọ wọn jẹ, ti nwọn nfi “ete aiyeraiye” Ọlọrun pamọ ti nwọn si nṣiṣẹ lodi si i nitôtọ, gan gẹgẹ bi “iru-ọmọ” Ejo Nla ti a fi oju ri lori ilẹ aiye. Ko si iṣọkan Kristian tôtọ ninu rẹ̀. Ọpọlọpọ abawọn ẹbi ẹjẹ li o wà lara aṣọ isin rẹ̀. Ko si mimu awọn eso ti ẹmi mimọ Ọlọrun dagba ninu rẹ̀, ni pataki ifẹ ará! Kakabẹ, “awọn iṣẹ ti ara” li o kún inu rẹ̀ fọ́fọ́! (Johannu 13:34, 35; Galatia 5:19-24) Sibẹ na, loju gbogbo ẹri Bibeli ti o ndẹbi fun u, o nsọ wipe on jẹ “Israeli Ọlọrun.”

5. Laibikita fun fifihan lọna odi lati ọdọ Kristendom, kini Ọlọrun ti bẹrẹsi ṣe ni ibamu pẹlu “ete aiyeraiye” rẹ̀?

5 Gbogbo fifi Ọlọrun han lọna odi yi ati Israeli rẹ̀ nipa ti ẹmi ha dí I lọwọ mimu “ete Aiyeraiye” Rẹ̀ ṣẹ pẹlu iyọrisi rere? Ki iṣe fun iṣẹju kan! On ti ri gbogbo eyi tẹlẹ o si ti sọtẹlẹ ninu akọsilẹ Ọrọ rẹ̀, Bibeli Mimọ. Majẹmu rẹ̀ titun pẹlu Israeli ti ẹmi ntẹsiwaju ninu agbara, ati, laisi aniani, o mba a lọ lati yan ati lati mura Israeli ti ẹmi silẹ fun ajọpin pẹlu Messiah na Jesu ninu ijọba ọrun ti a ṣeleri.

6. Ipo wo ni awọn ti o kẹhin ninu awọn 144,000 lori ilẹ aiye yio bọ si?

6 Niwọnbi iye awọn Israeli ti ẹmi ti a fi edidi dí fun ajumọjogun pẹlu Messiah na ninu ijọba ọrun li a fi mọ si 144,000 gẹgẹ bi Ifihan 7:4-8; 14:1-3 ti fihan, akoko na nilati de nigbati awọn ti o kẹhin ti a nfẹ fun ẹkunrẹrẹ iye ẹgbẹ Ijọba na di eyiti a ri lori ilẹ aiye. Dipo ki a pin wọn niya kelekele nipa isin gẹgẹ bi ti awọn ẹya isin Kristendom, ao ko wọn jọ papọ sinu iṣọkan ti ẹmi laibikita fun iran, awọ, orilẹ-ede tabi awọn isopọ ẹya. Niwọnbi nwọn ko ti jẹ apakan aiye yi, ao kore wọn kuro ninu aiye yi.—Johannu 17:14-23.

7. Kini Jesu fi iṣẹ ikojọpọ na wé, nibo li eyi si wà?

7 Oluwa na Jesu, nigbati o nṣalaye fun awọn aposteli rẹ̀ awọn ohun ijinlẹ tabi awọn “ohun ijinlẹ ijọba ọrun,” sọrọ nipa ikojọpọ ikẹhin yi fun “awọn ọmọ ijọba” wọnyi gẹgẹ bi “ikore” kan. O fihan igbati “ikore” ti ẹmi yi yio ṣẹlẹ, nigbati o wipe:

“Igbẹhin aiye ni ikore; awọn angeli si li awọn olukore. Nitorina gẹgẹ bi a ti ko epo jọ, ti a si fi ina sun wọn ; bẹni yio ri ni igbẹhin aiye. Ọmọ-enia yio rán awọn angeli rẹ̀, nwọn o si ko gbogbo ohun ti o mu-ni-kọsẹ ni ijọba rẹ̀ kuro, ati awọn ti o ndẹṣẹ. Yio si gọ wọn sinu ina ileru: nibẹ li ẹkun on ipahinkeke. yio gbe wà. Nigbana li awọn olododo yio má ràn bi ôrùn ni ijọba Baba wọn. Ẹniti o ba li eti ki o gbọ.”—Mattteu 13:11, 39-43.

8. “Ikore” ti ẹmi yi ha ni ohun kanṣoṣo ti yio ṣẹlẹ nigba “igbẹhin aiye,” ni idahun si ibere wo ni Jesu pese idahun na?

8 Ni “igbẹhin aiye” na, a sọtẹlẹ pe awọn nkan miran yio ṣẹlẹ ni afikun si kikore “awọn ọmọ ijọba.” (Matteu 24:31) Gbogbo awọn nkan miran wọnyi papọ pẹlu ikore ti ẹmi yio jẹ ami kan lati fi akoko na han ninu eyiti awa ngbe, pe o jẹ “igbẹhin aiye” ti a sọtẹlẹ. Jesu Messiah na, woli na ti o dabi Mose, to awọn nkan wọnyi lẹsẹsẹ ni idahun si ibere awọn aposteli rẹ̀ táràtà lẹhinti on ti sọtẹlẹ iparun tempili Jerusalemu. Nwọn bi i lere: “Nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? Kini yio si ṣe ami wiwa [Griki: parousia] rẹ ati ti opin aiye?”—Matteu 23:37 titi de 24:3.

9. Kini Jesu sọ asọtẹlẹ fun nigbana, nigbawo ni “akoko opin” Jerusalemu bẹrẹ, nigbawo li o si pari?

9 Ninu akọsilẹ Matteu 24:4-22 awa le kà, ni idahun, bi Jesu ti ṣe tun sọtẹlẹ iparun Jerusalemu, pẹlu awọn ogun, iyan, isẹlẹ, inunibini si awọn olotọ ọmọ-ẹhin rẹ̀, ẹṣẹ dida ti npọ si i ati ifẹ ti ntutu, iṣẹ iwasu lati ọwọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati isajade wọn kuro ni Judea ati Jerusalemu nigbati nwọn ba ri “ohun irira ti nsọ nidahoro ti o duro ni ibi mimọ.” Eyiyi nilati ṣẹlẹ ninu “iran yi” eyiti on ati awọn aposteli rẹ̀ jẹ apakan rẹ̀. Eyiyi tumọsi pe Jerusalemu ati eto awọn nkan ti a gbeka ori rẹ̀ gẹgẹ bi ibi ikorijọsi fun isin orilẹ-ede wa ninu “ọjọ ikẹhin” wọn. “Ikẹhin ọjọ” na bẹrẹ ni ọdun 29 C.E., nigbati Johannu Baptist bẹrẹsi wasu, “Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun ku si dẹdẹ,” ti o si baptisi Jesu nigbana, o si pari li ọdun 70 C.E. pẹlu isọdahoro Jerusalemu ati tempili rẹ̀ ati imukuro oyé alufa Aaroni. Jijẹ Ju ati isin Ju koiti jẹ ọkanna lati igbana.

AMI “IKẸHIN ỌJỌ”

10. Ninu asọtẹlẹ rẹ̀, bawo ni Jesu ṣe lo Jerusalemu ọgọrun ọdun kini, ti asọtẹlẹ rẹ̀ fi le kàn wa loni?

10 Biotiwukiori, Jesu sọrọ nipa ohun pupọ ti yio ṣẹlẹ lẹhinti a ba ti pa Jerusalemu run tan, wipe: Jerusalemu yio si di itẹmọlẹ li ẹsẹ awọn keferi, titi akoko awọn keferi yio fi kun.” (Luku 21:20-24) O ṣe kedere, lẹhin fifi pẹlu iṣọra ṣe ayẹwo asọtẹlẹ Jesu ni kikun, gẹgẹ bi a ti ri i ninu Matteu, ori kẹrinlelogun ati karundinlọgbọn, Marku, ori kẹtala, ati Luku, ori kọkanlelogun, pe Jesu nlo Jerusalemu ọgọrun ọdun ekini gẹgẹ bi apẹrẹ asọtẹlẹ ekeji rẹ̀ ti ode oni pẹlu, Kristendom, ati eto awọn nkan ti nṣẹlẹ larin awọn Ju ti a tuka kiri gbogbo aiye gẹgẹ bi apẹrẹ kan fun eto awọn nkan jakejado aiye li ode oni, ti Kristendormn jẹgaba le lori. Nitorina asọtẹlẹ Jesu lori “igbẹhin aiye” tun kan ti ọjọ oni pẹlu, fun imuṣẹ rẹ̀ ni kikun. Eṣe ti a fi wipe “oni”? O ha tumọsi pe awa ti a waláyé loni ngbe ni “igbẹhin aiye” na ti a sọtẹlẹ bi? Bẹni!

11. Ni igba akoko wo ni aiye yi bá ara rẹ̀, eyiyi ṣe deédé pẹlu awọn igba akoko wo ti o ri bakanna tẹlẹri?

11 Aiye loni ngbe ninu “igbẹhin aiye!” rẹ̀. Ẹ Jẹki a ranti bi a ti ṣe fi ikun omi agbaiye pa “aiye igbani,” “aiye awọn alaiwa-bi-Ọlọrun,” “aiye ti o wa nigbana,” ti akoko Noa run, pe “akoko opin” rẹ̀ bẹrẹ ni ọgọfa ọdun ṣaju jamba omi ti 2370 B.C.E. (2 Peteru 2:5; 3:6; Genesisi 6:1-3; Matteu 24:37-39) Ṣaju iparun Jerusalemu ni 607 B.C.E. lati ọwọ awọn ara Babiloni, Ọlọrun ba ọba ti o jẹ kẹhin ni ila idile Dafidi lori itẹ Jerusalemu, Sedekiah sọrọ, o si tọka si “igba aiṣedede ikẹhin.” “Ikẹhin ọjọ” fun Jerusalemu nigbana jẹ ogoji ọdun ni gigun, ti o bẹrẹ nigbati Ọlọrun gbe Jeremiah dide lati jẹ woli rẹ̀ ni ọdun kẹtala ijọba Josiah. (Esekieli 21:25; Jeremiah 1:1, 2; Esekieli 4:6, 7) Jerusalemu ọgọrun ọdun ekini C.E. ní “ikẹhin ọjọ” rẹ̀ pẹlu ti o jẹ ọkanlelogoji ọdun (29-70 C.E.).—Luku 19:41-44; 1 Tessalonika 2:16.

12. Woli wo ni Jehofah lò lati mẹnuba “akoko opin,” ki si ni ohun ti o fihan lati 1914 C.E. pe a wà ninu akoko na?

12 Ọpọ ọdun lẹhin iparun akọkọ fun Jerusalemu lati ọwọ awọn ara Babiloni, angeli Ọlọrun ba woli Danieli sọrọ nipa “ọjọ ikẹhin” eyiti yio de sori eto awọn nkan jakejado aiye. (Danieli 11:35 titi de 12:4) Awa ti wà ninu “ikẹhin ọjọ” na lati ọdun 1914 C.E. Awa sọ eyi, ki iṣe nitoripe li ọdun na Ogun Agbaiye Kini bẹsilẹ nikan ni ti o si mu sanmani iwa-ipa ati agbara ogun eyiti o nfẹjumọ pipa gbogbo iran enia run kuro lori ilẹ aiye. Otitọ ni pe lati igba ọdun pataki na ni asọtẹlẹ Jesu nipa “ami” opin eto awọn nkan ti nni imuṣẹ ni kikun. Niwọnbi “ikẹhin ọjọ” yi yio ti pari si ohun ti Jesu pe ni “ipọnju nla, iru eyiti ko si lati ibẹrẹ ọjọ ìwa di isisiyi, bẹkọ iru rẹ̀ ki yio si si,” o tumọsi pe awa nsunmọ aṣepari opin eto awọn nkan isisiyi, ati pẹlu rẹ̀ iparun. “aiye awọn alaiwa-bi-Ọlọrun.”—Matteu 24:21.

13. (a) Bawo ni Matteu 24:14 ṣe fihan pe “wiwa-nihin” Kristi nilati jẹ nipa ijọba Ọlọrun? (b) Niwọnbi Kristi ko ti dá ọjọ funni, iṣoro wo li o dide?

13 Sibẹ, idi na ti a fi nilati fi ọdun na 1914 C.E. si ọkàn ni pe li ọdun na ni “wiwa-nihin” (parousia) Jesu Oluwa ninu aṣẹ ijọba Messiah bẹrẹ. Pe “wiwa-nihin” rẹ̀ li aiṣe fojuri jẹ otitọ li ọna bayi li a fihan nipasẹ ohun pataki kan ti on wi ni didahun ibere awọn aposteli nipa “ami wiwa rẹ.” On ni yi, gẹgẹ bi a ti ṣe kọ ọ silẹ ninu Matteu 24:14: “A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede; nigbana li opin yio si de.” Nigbati o ndá awọn aposteli rẹ̀ lohun, Jesu ko funni li ọjọ, sibẹ ifihan “ami” lati ọdun na 1914 siwaju titi di isisiyi sami si ọdun na gẹgẹ bi akoko bibi ijọba Messiah Ọlọrun li ọwọ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi li ọrun. Ṣugbọn ọna miran tun wà fun mimọ ọjọ na lati jẹri si i pe o jẹ akoko kan ti a ti yàn tẹlẹ fun bibi ijọba Ọlọrun pẹlu “wiwa-nihin” Kristi ninu rẹ̀. Kini ọna miran na fun mimọ̀ 1914?

14. Nigbawo ni Akoko Awọn Keferi ti Jesu mẹnukan bẹrẹ, rekọja iṣẹlẹ wo ni nwọn si nilati má ba a lọ?

14 Ninu asọtẹlẹ rẹ̀ niti “Nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ?” o sọtẹlẹ nipa iparun Jerusalemu ti o sunmọle o si fikun u pe: “Jerusalemu yio si di itẹmọlẹ li ẹsẹ awọn keferi, titi akoko ti a dá fun awọn keferi yio fi kún.” (Luku 21:20-24) “Akoko ti a dá fun awọn keferi [orilẹ-ede, ti ki iṣe Ju]” bẹrẹ ni 607 B.C.E. nigbati awọn ara Babiloni pa Jerusalemu run ti nwọn si bì atọmọdọmọ Ọba Dafidi ti njọba ṣubu, ati ajogun majẹmu atọrunwa fun ijọba ainipẹkun kan. Akoko Awọn Keferi wọnyi, gẹgẹ bi a ti saba má npe wọn, mba a lọ titi di ọjọ Jesu nwọn yio si má ba a lọ lẹhin iparun ilu mimọ na lékeji. O jẹ otitọ pe lẹhin adọrin ọdun iparun Jerusalemu ati ilẹ Juda iyoku olôòtọ awọn Ju pada lati oko ẹrú ni ilẹ Babiloni nwọn si tún Jerusalemu kọ ati awọn ilu miran ni ilẹ ti a ti sọ di ahoro tipẹtipẹ, Sugbọn eyini ko tumọsi pe Jerusalemu ti ṣiwọ didi itẹmọlẹ lati ọwọ awọn Keferi, lakọkọ lati ọwọ awọn ara Babiloni ati lẹkeji lati ọwọ awọn Medo-Persia ti o ṣẹgun Babiloni.

15. (a) Eṣe ti Akoko awọn Keferi nilati má ba a lọ lẹhinti a tun Jerusalemu kọ ni 537 B.C.E.? (b) Eṣe ti awọn Akoko wọnni fi mba a lọ lẹhin idanwo Jesu niwaju Pontiu Pilatu?

15 Eṣe? Nitoripe, pẹlu atunkọ Jerusalemu lati 537 B.C.E. siwaju, itẹ ati ijọba Messiah ti ila idile ọba Dafidi li a ko mu padabọ si Jerusalemu. Nisisiyi Jerusalemu wà ni agbegbe kan ni Ilẹ Ọba Medo-Persia o si wà labẹ ijẹgaba Dariusi ara Media ati Kirusi Nla, ara Persia. Nitorina ohun ti Jerusalemu ti duro fun lati igbati a ti ṣẹgun rẹ̀ lati ọwọ Ọba Dafidi li ọdun 1070 B.C.E. ṣi wà labẹ: itẹmọlẹ, eyini ni, ipo Jerusalemu gẹgẹ bi olu ilu ijọba Messiah ti awọn ọmọ ati awọn arọpo Ọba Dafidi. Ijọba awọn Maecabee ti awọn alakoso Lefi (104-63 ati 40-37 B.C.E.) ko yi otitọ na pada. Nigbana, nigbati Jesu “ọmọ Dafidi” wá ti o si fi ara rẹ̀ han gẹgẹ bi ẹnikan ti Ọlọrun fi ororo ẹmi rẹ̀ yan, eyiti o pọ julọ ninu awọn aṣaju isin Ju ati awọn ọmọlẹhin wọn ko fẹ ẹ gẹgẹ bi Messiah ati Ọba wọn. Nwọn kigbe sode fun Pontiu Pilatu Gomina Romu na pe: “Awa ko li ọba bikoṣe Kesari.” (Johannu 19:15) Nitorina Akoko Awọn Keferi ntẹsiwaju, ẹtọ si jijẹ ọba Messiah li a si ntẹmọlẹ siwaju si i.

16, 17. (a) Nitori imuṣẹ asọtẹlẹ Jesu, a sọ wipe Akoko awọn Keferi kún nigbawo? (b) Ọba igbánì wo ni Ọlọrun fi gigun akoko han fun, bawo li Ọlọrun si ti ṣe lo ọba yi?

16 Sugbọn, Jesu wipe: “Titi akoko ti a dá fun awọn keferi yio fi kún.” Titi di igba wo lẹhinti Babiloni ti bì itẹ Ọba Dafidi ṣubu ni Jerusalemu ni 607 B.C.E. ni akoko awọn keferi wọnni ti nṣe idiwọ fun ijọba Messiah Ọlọrun yio fi ma ba a lọ?

17 Nisisiyi, nitôtọ, lẹhin riri ohun ti o ti ṣẹlẹ ni imuṣẹ asọtẹlẹ Jesu lati igba ti Ogun Agbaiye Kini bẹ silẹ, awa le fi pẹlu idaniloju dahun pe, Titi di igbati Akoko Awọn Keferi yio fi pé ni 1914 C.E. Bẹni, ṣugbọn, ju eyini lọ, li ọjọ Ọba Nebukadnessari, ẹniti o pa Jerusalemu run ni 607 B.C.E., Ọlọrun fihan pe on ti sami si bi Akoko Awọn Keferi wọnni yio ti gùn to, ti o bẹrẹ nigbana ti yio si ma ba a lọ titi laisi idilọwọ lati ọdọ ijọba Messiah Ọlọrun. Ọlọrun fihan pe yio jẹ “igba” iṣapẹrẹ meje. Àlá na ninu eyiti Ọlọrun fi igba akoko yi han fun Nebukadnessari ni woli Danieli tumọ rẹ̀. (Danieli 4:16, 23, 25, 32) Ọlọrun lò Nebukadnessari gẹgẹ bi agegi kan lati ge lulẹ ifihan ijọba Ọlọrun lori ilẹ aiye ni Jerusalemu ni 607 B.C.E. Kukute “igi” iṣapẹrẹ na li a nilati dé ki a má si gbàa láyè lati ruwe ki o si pese igi titun ayafi igba ti “igba meje?” ba kọja.

18. (a) Nigba Akoko awọn Keferi wọnni iṣakoso ijọba tí ila idile ọba Dafidi nilati lò ni tani lò, ni iru ọna wo si ni? (b) Bawo li a ṣe ṣapẹrẹ imupadabọsipo iṣakoso Messiah?

18 Nisisiyi, nigba “igba meje” wọnni, awọn agbara aiye keferi yio lo agbara iṣakoso eyiti o jẹ ti ila idile Ọba Dafidi niti tôtọ nitori majẹmu ti Ọlọrun ti ba a dá fun ijọba ainipẹkun. Ṣugbọn awọn Keferi alakoso wọnni lo agbara iṣakoso na lọna ti ki iṣe ti ijọba Ọlọrun, lọna ti o lodi si Messiah, gẹgẹ bi ti alailọgbọn ninu iru eyiti Nebukadnessari fihan nigba ọdun meje wẹ̀rẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn gan gẹgẹ bi a ti mu Nebukadnessari pada bọ sipo si ijọba li opin ọdun meje wọnni nigbati orirẹ̀ pé tan, bẹ gẹgẹ ni ami ijọba Messiah Ọlọrun di eyiti a mu padabọ sipo li opin “igba meje” ijẹgaba aiye Keferi. Nigbana kukute ijọba li a ko tun dè mọ, lati inu awọn gbongbo rẹ̀ ni igi titun ti iṣakoso si nilati dagba soke.—Danieli 4:1-37.

19, (a) Niti pe iye Akoko awọn Keferi na jẹ meje, bawo ni “akoko” Ọkan yio ti gùn to? (b) Nkan bi akoko wo li ọdun ni pg177 awọn akoko wọnni bẹrẹ, ati ni nkan bi akoko ọdun wo ni yio dopin?

19 Nisisiyi bi a ba ṣiro pada sẹhin lati 1914 C.E. si 607 B.C.E., o jẹ 2,520 ọdun li apapọ. Bi a ba si tun mu iye na “igba” meje, ti a si pin i si ọdun meje, yio jẹ 360 ọdun. Eyini ni gigun “igba” iṣapẹrẹ kan ninu Iwe Mimọ. (Ifihan 12:6, 14; fi we Ifihan 11:2, 3.) Ọdun meje gidi ti Nebukadnessari fi sinwin ṣapejuwe awọn “igba meje” wọnni ti 2,520 ọdun, ti ọjọ kọkan iṣapẹrẹ “igba” ti 360 ọjọ si duro fun ọdun kan. (Esekieli 4:6; Numeri 14:34) “Igba meje” iṣapẹrẹ na bẹrẹ nigbati awọn ọmọ ogun Babiloni fi Jerusalemu ati ilẹ Juda silẹ li ahoro, laisi gomina lati rọpo Gomina Gedaliah ti a pa ni ilẹ na, ni nkan bi idaji oṣu oṣupa na Tishri. Nitorina nwọn yio dopin ni nkan bi akoko na li ọdun 1914 C.E., tabi ni nkan bi October 4/5, 1914.

20. Kini yio tumọsi nigbati odikeji rẹ̀ ba ṣẹlẹ ni 1914 C.E. nipa ohun ti o ṣẹlẹ ni 607 B.C.E.?

20 Ni akoko ti o kẹhin yi odikeji ohun ti o ṣẹlẹ ni Tishri 607 B.C.E. ni yio ṣẹlẹ, nigbati Akoko Awọn Keferi bẹrẹ. A fi ilẹ Juda silẹ li ahoro lasan laisi tempili kankan ni Jerusalemu, laisi “itẹ [Jehofah]” nibẹ pẹlu atọmọdọmọ Ọba Dafidi ti a fi ami ororo yan ti o joko lori rẹ̀. (1 Kronika 29:23) Eyiti tumọsi pe ni ibẹrẹ ikore ti 1914 C.E. titẹmọlẹ ijọba Messiah lati ọwọ awọn orilẹ-ede Keferi nilati dopin a si nilati bí ijọba Messiah, ki iṣe ni Jerusalemu ori ilẹ aiye, ṣugbọn li oke ọrun nibiti Ọmọ ati Oluwa Ọba Dafidi joko nisisiyi li ọwọ ọtun Jehofah Ọlọrun. (Orin Dafidi 110: 1, 2) Nigbana li o jẹ pe ẹni ami ororo na de “ẹniti o li ẹtọ si i,” Jehofah si fi fun u.—Esekieli 21:25-27; Danieli 7:13, 14.

21. Bawo li a ti ṣe ṣapẹrẹ bibi ijọba Messiah Ọlọrun li ọrun, kini sì tẹle e lẹsẹkẹsẹ?

21 Ogun Agbaiye Kini ti ju oṣu meji lọ ti o fi nja nigbati iṣẹlẹ yiyanilẹnu na ṣẹlẹ ninu awọn ọrun ti ko ṣe fojuri. Ninu Ifihan 12:1-5 ijọba Messiah titun na ti a ṣẹṣẹ bi li a fi ọmọkunrin kan ṣapẹrẹ eyiti “obirin” Ọlọrun li ọrun bí eyiti a si gbe lọ si ori itẹ Ọlọrun lati ṣe ajọpin iṣakoso pẹlu Rẹ. Nitori na apa pataki ninu “ete aiyeraiye” Ọlọrun yi ṣẹgun, ṣugbọn lodisi atako awọn ẹda ti o ju enia lọ. Lori eyi a kà pe:

“Ogun si mbẹ li ọrun: Mikaeli ati awọn angeli rẹ̀ ba ikoko na jagun; ikôkò si jagun ati awọn angeli rẹ̀. Nwọn ko si le ṣẹgun; bẹni a ko si ri ipo wọn mọ li ọrun. A si lé ikôkò nla na jade, ejo lailai nì, ti a npe ni Eṣu, ati Satani, ti ntan gbogbo aiye jẹ: a si lé e jù si ilẹ aiye, a si lé awọn angeli rẹ̀ jade pẹlu rẹ̀. Mo si gbọ ohùn rara li ọrun, nwipe:

“Nigbayi ni igbala de, ati agbara, ati ijọba Ọlọrun wa, ati ọla ti Kristi rẹ̀; nitori a ti lé olufisun awọn arakunrin wa jade, ti o nfi wọn sùn niwaju Ọlọrun wa lọsan ati loru. Nwọn si ṣẹgun rẹ̀ nitori ẹjẹ Ọdọ agutan na, ati nitori ẹri wọn, nwọn ko si fẹran ẹmi wọn ani titi de iku, Nitorina ẹ má; yọ, ẹnyin ọrun, ati ẹnyin ti ngbe inu wọn. Egbé ni fun aiye ati fun okun! nitori Eṣu sọkalẹ tọ̀ nyin wá ni ibinu nla, nitori o mọ̀ pe igba kukuru ṣá li on ni.

“Nigbati ikoko na ri i pe a lé on lọ si ilẹ aiye, o ṣe inunibini si obirin ti o bí ọmọkunrin na... .. Ikokò na si binu gidigidi si obirin na, o si lọ ba awọn iru-ọmọ rẹ̀ iyoku jagun, ti nwọn npa ofin Ọlọrun mọ, ti nwọn si di ẹri Jesu mu.”—Ifihan 12:7-17.

22. (a) Fifi ti Mikaeli fi Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ sọko kuro li ọrun fi kini han niti bi on ti ṣe jẹ? (b) Bawo ni Jesu ṣe sọ asọtẹlẹ awọn inunibini ti o de sori “iyoku iru-ọmọ [obirin]” na?

22 Bẹni, olori awọn angeli na Mikaeli fi ara rẹ̀ han lẹkansi i li ọrun, gẹgẹ bi “iru-ọmọ” “obirin” Ọlọrun ti a ti pinnu lati fọ ori Ejo na, o bori ninu ogun na o si fi Ejo lailai nì ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ sọko si ilẹ aiye. Ninu ibinu rẹ̀, Ejo Nla ha ṣe inunibini si “obirin” na nipa ṣiṣe inunibini si “iyoku iru-ọmọ rẹ̀” ti o ba ara wọn li ori ilẹ aiye nigba ati lati igba Ogun Agbaiye Kini. Ninu asọtẹlẹ rẹ̀ Jesu sọtẹlẹ iru inunibini bẹ fun awọn ẹni ami ororo ọmọlẹhin rẹ̀ pe o nilati ṣẹlẹ nigba “opin eto awọn nkan.” O wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe:

“Nigbana ni nwọn o fi nyin funni lati jẹ ni ìyà, nwọn o si pa nyin: a o si korira nyin lọdọ gbogbo orilẹ-ede nitori orukọ mi. .... Ṣugbọn ẹniti o ba foriti i titi de opin, on na li a o gbala.”—Matteu 24:9-13.

23. (a) Iyoku ẹni ami ororo na ti fi ara wọn han nipa ṣiṣe igbọran si aṣẹ wo ti a pa nipasẹ Jesu? (b) Bẹrẹ lati igba wo ni a ti nkede ọdun na fun Akoko Awọn Keferi lati dopin?

23 Nitorina ẹri na mbẹ li ọwọ, lati inu Bibeli ati lati inu itan aiye, pe “akoko opin” na bẹrẹ ni ibẹrẹ iruwe 1914. Ni ẹri kikun pẹlu otitọ yi, inunibini na mba a lọ fun iyoku awọn ẹni ami ororo, ti “npa ofin Ọlọrun mọ, ti nwọn si di ẹri Jesu mu.” Awọn wọnyi li awọn ẹniti o npa ofin Ọlọrun mọ ti o wà ninu asọtẹlẹ Jesu:

“A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede.” (Matteu 24:14) Iyoku awọn ẹni ami ororo yi ti fi ara wọn han ninu awọn oju iwe itan lati 1914 wá. Ṣaju ọdun yi awọn memba iyoku awọn ẹni ami ororo yi ti nfi pẹlu itara kẹkọ Ọrọ Ọlọrun yatọ si Kristendom. Nwọn fi Bibeli Mimọ si iwaju awọn isin atọwọdọwọ ti enia ṣe. Ni nkan bi 1876 nwọn ti nkede pe Akoko Awọn Keferi ti 2,250 ọdun yio pari ni ọdun 1914. Awọn ohun ti o ti ṣẹlẹ lati ọdun na wá fihan pe nwọn ko ṣe aṣiṣe.

24. (a) Nigba Ogun Agbaiye Kini, eṣe ti iyoku na fi di ohun ikorira jakejado aiye? (b) Iru iṣẹ lẹhin ogun wo ni nwọn bẹrẹsi ṣe, orukọ wo ni nwọn si nlepa lati sọ di mimọ̀?

24 Nigba Ogun Agbaiye Kini nwọn di ohun ikorira lati ọdọ gbogbo orilẹ-ede nwọn si jiya inunibini lilekoko nitoripe nwọn faramọ ijọba Messiah Ọlọrun ti nwọn si gbiyanju lati yọwọ-yọsẹ kuro ninu ẹbi ẹjẹ eyiti Kristendom fi mba ara rẹ̀ jẹ. Ni 1919, ọdun ekini lẹhin ogun, nwọn loye ẹrù iṣẹ aigbọdọmaṣe Kristian wọn lati kede ju ti igbakigba ri lọ ijọba Messiah Ọlọrun, ti a ti gbekalẹ li ọrun li opin Akoko Awọn Keferi ni 1914. (Matteu 24:14) Li ọdun na 1925 oju imoye wọn ti ẹmi li a ṣí lati ri i pe akoko na de fun Ọlọrun lati sọ orukọ kan fun ara rẹ̀. (2 Samueli 7:23; Jeremiah 32:20; Isaiah 63:14; wo The Watch Tower labẹ ọjọ August 1, 1925, oju iwe 226, apa 2, ẹsẹ 4, pẹlupẹlu September 15, 1925, oju iwe 280 ẹsẹ 41-43.) Nitorina nisisiyi nwọn fi ara wọn fun iṣẹ sisọ di mimọ jakejado aiye orukọ inu Bibeli fun Ọlọrun aláyè ati otitọ na ati “ete aiyeraiye” rẹ̀ “ti o ti pinnu ninu Kristi Jesu Oluwa wa.”—Efesu 3:11.

25. Lati inu kini ni iyoku ẹni ami ororo yẹ ki o pa ara rẹ̀ mọ, nitorina kini nwọn tẹwọgba ni 1931 C.E.?

25 Nitorina ni ọdun 1931, laisi igberaga ṣugbọn pẹlu idalare kikun fun ẹsẹ ti a gbe nisisiyi, nwọn tẹwọgba orukọ kan ti yio fi wọn han yatọ kuro ninu Babiloni Nla, ilẹ ọba isin eke agbaiye, lati inu eyiti nwọn ti jade wá ni igbọran si aṣẹ Ọlọrun ninu Ifihan 18:4. Bẹni, orukọ kan ti yio mu wọn yatọ pápá si Kristendom pẹlu ọgọrọrun awọn ẹya isin rẹ̀ ti o lodi si ara wọn ati jijẹ onifẹ aiye rẹ̀ ati ẹbi ẹjẹ lọna pupọ. Nitotọ, orukọ kan ti a gbeka ori Iwe Mimọ (Isaiah 43:10, 12) eyini yio si fi si iwaju wọn ni kedere iṣẹ Kristian wọn. O jẹ orukọ kan ti a ti mọ̀ nigba pipẹ jakejado aiye, orukọ kan ti a nbọla fun ti a si nkorira rẹ̀, eyini ni, Ẹlẹri Jehofah. Nwọn nrin ni yiyẹ orukọ yi!

“OGUNLỌGỌ NLA” KAN TI YIO LA HAR-MAGEDON JÁ

26. Lati igba pipẹ wo sẹhin ni Ọlọrun ti nyan “awọn enia fun orukọ rẹ̀,” On ha ṣe alaini iru awọn enia bẹ loni bi?

26 Gbogbo eyi ha iṣe ibújade itara isin kan ti ko wà pẹ́ titi bi? Ihaṣe akọsẹba kan lasan ti ko nilari bi? Tabi eyi ha iṣe ni ibami pẹlu ete Ọlọrun ti ntẹsiwaju? Wo abajade rẹ̀! Ohun kan ti a mọmọ̀ bẹrẹ rẹ̀ lẹhin lọhun ni Jerusalemu ni ọjọ pataki na ti Pentikosti 33 C.E. nigbati Ọlọrun tú ẹmi mimọ rẹ̀ jade ti aposteli Peteru ti o kún fun ẹmì mimọ dide duro ti o si fa asọtẹlẹ Joeli 2:28-32 yọ ti o si wi fun awọn ẹgbẹgbẹrun awọn Ju pe: “Ẹnikẹni ti o ba ke pe orukọ [Jehofah] li a o gbala.” Nibẹ li Ọlọrun ti bẹrẹsi “yan enia fun orukọ rẹ̀,” Israeli ti ẹmi. (Iṣe 2:1-21; 15:14) Igbesẹ miran siwaju li a tun gbe li opin ‘adọrin ọsẹ ọdun’ ni 36 C.E., nigbati Ọlọrun rán aposteli Peteru lati wásu fun awọn Keferi alaikọla ti o si tú ẹmi mimọ rẹ̀ jade sori awọn onigbagbọ wọnyi ti ki iṣe Ju. Nipa bayi Ọlọrun mu awọn “enia fun orukọ rẹ̀” pọ si i nipa bibaptisi ati fifi ami ororo yan awọn Keferi pẹlu ẹmì mimọ ti o si nfi wọn kún Israeli rẹ̀ ti ẹmi. (Iṣe 10:1 titi de 11:18; 15:7-11) Eyini ṣẹlẹ lẹhin lọhun ni ọgọrun ọdun ekini. Nipa ti ode oni nkọ, ni ọgọrun ọdun lọna ogun yi? Awọn otitọ itan ti a ko le janikoro fihan pe Ọlọrun ti ṣe aṣeyọri ni yiyan “awọn enia fun orukọ rẹ̀” sibẹ!

27. Nitorina ẹri wo li a ni loni pe Ọlọrun ti rọ̀ mọ ete rẹ̀ nipa eyi, awọn ibukun lati inu eyi si nlọ sọdọ tani loni?

27 Wiwà lori ilẹ aiye iyoku ikẹhin fun “iru-ọmọ” Abrahamu nipa ti ẹmi loni jẹri si i pe Ọlọrun nṣe aṣepari ikojọpọ iye 144,000 Israeli ti ẹmi na ni kikun labẹ Ori wọn, Jesu Kristi. Eyiyi ri bẹ laibikita fun gbogbo atako lati ọdọ awọn ẹmi eṣu ati enia! “Ipinnu ataiyebaiye” rẹ̀ “ti o ti pinnu ninu Kristi” nṣe aṣeyọri—nisisiyi! On ti pinnu laisi iyipada kankan lati ri ete rẹ̀ ti o nṣe aṣeyọri sinu opin rẹ̀ ti o mu iṣẹgun lọwọ ni kikun laipẹ lọjọ iwaju. Wo rere ti eyi yio ṣe fun enia! “Ogunlọgọ” enia ti o mọriri otitọ yi npọ si i jakejado aiye. Nisisiyi nwọn nri ibukun gba nipasẹ iyoku Ọlọrun ti “iru-ọmọ” Abrahamu ti ẹmi.

28. Tani “iru-ọmọ” Abrahamu ni pataki, ṣugbọn kini fihan boya ibukun na mọ si ọdọ kiki awọn wọnni ti o jẹ memba “iru-ọmọ” na?

28 Abrahamu babanla igbánì nṣapẹrẹ Jehofah Ọlọrun. Jehofah funrarẹ̀ ni Abrahamu Titobiju. “Iru-ọmọ” rẹ̀ ni pataki ni Ọmọ rẹ̀ ti a ti fi rubọ nigbakanri, Jesu Kristi Oluwa wa. Nipasẹ Olori ninu “iru-ọmọ” yi pãpã li a gba bukun gbogbo memba Israeli ti ẹmi. Ṣugbọn ibukun na ha simi si ọdọ wọn? Bẹkọ! Ileri ti Ọlọrun bura fun Abrahamu igbánì ni: “Ninu iru-ọmọ rẹ li a o bukun fun gbogbo orilẹ-ede aiye.” (Genesisi 22:18; Iṣe 3:22-26) “Iru-ọmọ” yi ní ninu ju Jesu Kristi nikan, nitoripe iru-ọmọ Abrahamu nilati dabi irawọ oju ọrun ati yanrin eti okun—ainiye. Nitori na, “iru-ọmọ” na kàn gbogbo Israeli ti ẹmi. Nipasẹ “iru-ọmọ” yi li apapọ awọn miran yio ri ibukun gba fun ara wọn, bẹni, “gbogbo orilẹ-ede aiye” lẹhinode “iru-ọmọ!” na, lẹhin ode Israeli ti ẹmi. Nitorina gbogbo araiye li ao bukun fun nipasẹ “iru-ọmọ” Abrahamu Titobiju, Jehofah Ọlọrun, Baba ọrun “iru-ọmọ” ti ẹmi. Pẹlu opin yi li ọkàn ajinde awọn oku yio wà labẹ ijọba Messiah “iru-ọmọ” na.—Iṣe 24:15.

29, 30. (a) Ṣaju akoko awọn Kristian, tani ṣapẹrẹ awọn wọnni ti ngba ibukun nisisiyi nipasẹ iyoku “iru-ọmọ” na? (b) Bawo ni Jesu ṣe tọkasi awọn olu-la “ipọnju nla” ti mbọ wa já?

29 Tani loni ninu gbogbo orilẹ-ede ni awọn wọnni ti nri ibukun gba nipasẹ tabi ni ikẹgbẹpọ pẹlu “iyoku” “iru-ọmọ” Abrahamu? Gẹgẹ bi ete onifẹ Ọlọrun, awọn wọnyi li a ti ṣapẹrẹ rẹ̀ nigba pipẹ sẹhin. Nipasẹ tani?

30 Lọhun ni 1513 B.C.E., nigbati awọn ọmọ Israeli ti a dá nídè kuro ni Egipti lẹhin alẹ Irekọja ti nwọn si la Okun Pupa já lẹhinna si igbala li etikun Sinai ti omi fẹrẹ yika, “ọpọ enia” ti ki iṣe ọmọ Israeli darapọ mọ wọn. (Eksodu 12:38; Numeri 11:4) Ni 607 B.C.E., nigbati awọn ọmọ ogun Babiloni pa Jerusalemu run fun igba ekini, iwẹfa ara Etiopia, Ebedemeleki ati awọn Rekabu ti ki iṣe ọmọ Israeli wà ti o la iparun ilu mimọ na ati tempili rẹ̀ ja. (Jeremiah 35:1-19; 38:7-12; 39: 16-18) Ni Nisani 33 C.E. nigbati Jesu sọ asọtẹlẹ iparun ti yio de sori Jerusalemu li ọdun 70 C.E. ti eyini si jẹ apẹrẹ iru iparun fun Kristendom ninu iran tiwa, o wipe:

“Nitori nigbana ni ipọnju nla yio wà, iru eyi ti ko si lati igba ibẹrẹ ọjọ ìwa di isisiyi, bẹkọ, iru rẹ̀ ki yio si si. Bi ko si ṣepe a ké ọjọ wọnni kuru, ko si ẹda ti iba le là a; ṣugbọn nitori awọn ayanfẹ li ao fi ké ọjọ wọnni kuru.”—Matteu 24:21, 22; Marku 13:19, 20.

31. Iran wo li a fifun aposteli Johannu nipa “ogunlọgọ” nla na ti o la “ipọnju nla” na ja pẹlu iyoku ti ẹmi na?

31 Ni afikun si iyoku Israeli ti ẹmi, tabi “awọn ayan fẹ,” awọn olulà a ja miran yio wà lati inu “ipọnju nla!” na ti o sunmọle. Ni nkan bi ọdun na 96 C.E., aposteli Johannu arugbo na li a fun ni iran awọn wọnyi ti o là “ipọnju nla” na já li apapọ pẹlu “iyoku” Israeli ti ẹmi. Ni kete lẹhin riri iran fifi edidi dí Israeli ti ẹmi na awọn 144,000 olotọ memba ti ẹmi, Johannu mba a lọ lati wipe:

“Lẹhin na, mo ri, si kiyesi i, ọpọlọpọ enia ti ẹnikẹni ko le kà, lati inu orilẹ-ede gbogbo, ati ẹya, ati enia, ati lati inu ede gbogbo wa, nwọn duro niwaju itẹ, ati niwaju Ọdọ-Agutan na, a wọ wọn li aṣọ funfun, imọ ọpẹ si mbẹ li ọwọ wọn; nwọn si kigbe li ohùn rara, wipe, Igbala ni ti Ọlọrun wa ti o joko lori itẹ, ati ti Ọdọ-Agutan.

“Ọkan ninu awọn agba na si dahun, o bi mi pe, Tali awọn wọnyi ti a wọ li aṣọ funfun ni? Nibo ni nwọn si ti wá? Mo si wi fun u pe, Oluwa mi, Iwọ li o le mọ̀. O si wi fun mi pe, Awọn wọnyi li o jade lati inu ipọnju nla, nwọn si fọ aṣọ wọn, nwọn si sọ wọn di funfun ninu ẹjẹ Ọdọ-Agutan na. Nitorina ni nwọn ṣe mbẹ niwaju itẹ Ọlọrun. Ti nwọn si nsìn i li ọsan ati li oru ninu tempili rẹ̀. Ẹniti o joko lori itẹ na yio si ṣiji bò wọn. Ebi ki yio pa wọn mọ, bẹli ongbẹ ki yio gbẹ wọn mọ. Bẹli ôòrùn ki yio pa wọn mọ tabi orukoru. Nitori Ọdọ-Agutan ti mbẹ li arin itẹ na ni yio má ṣe oluṣọ-agutan wọn. Ti yio si ma ṣe amọna wọn si ibi orisun omi iye. Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn.”—Ifihan 7:9, 10, 13-17.

32. (a) Nigbawo li a kọkọ tẹ alaye ti o ṣe dédé pẹlu awọn otitọ ọjọ wa jade nipa iran yi? (b) Eṣe ti a fi nilati reti pe awọn wọnni ti o jẹ ti “ogunlọgọ nla” ko ni lọ si ọrun ki nwọn si jọba pẹlu Ọdọ-agutan Ọlọrun?

32 Alaye itumọ iran yi ti o ba awọn otitọ ọjọ na mu li a fidi rẹ̀ mulẹ lakọkọ li ọdun 1935 C.E., bẹrẹ pẹlu ipade awọn Kristian ẹlẹri Jehofah ti a ṣe ni Washington (D.C.) ni May 31, 1935. “Ọpọlọpọ enia” tabi “Ogunlọgọ nla” ti a ri ninu iran na ko reti lati lọ si ọrun ki nwọn si jọba lori Oke Sioni pẹlu awọn 144,000 Israeli ti ẹmi. Fun apẹrẹ, ninu Ifihan 14:1-3 a kà pe kiki awọn wọnni ti o duro pẹlu Ọdọ-Agutan Ọlọrun lori Oke Sioni li ọrun ni awọn 144,000 Israeli ti ẹmi. A ko ri “ogunlọgọ nla” na ki o duro nibẹ, ati fun idi rere si ni. Afi kiki 144,000 li a wi nipa rẹ̀ pe: “Awọn wọnyi li a rà pada lati inu awọn enia wa, nwọn jẹ akọso fun Ọlọrun ati fun Ọdọ-Agutan na.” (Ifihan 14: 4, 5; Jakọbu 1:18) Nipa 144,000 ti “a rà pada lati inu aiye wa,” a ka awọn ọrọ wọnyi ti a sọ fun Ọdọ-Agutan Ọlọrun:

“A ti pa ọ, iwọ si ti fi ẹjẹ rẹ ṣe irapada enia si Ọlọrun lati inu ẹya gbogbo, ati ede gbogbo, ati enia gbogbo, ati orilẹ-ede gbogbo wa. Iwọ si ti ṣe wọn li ọba ati alufa si Ọlọrun wa. Nwọn si njọba lori ilẹ aiye.”—Ifihan 5:9, 10.

33. Ninu tani, nigbana, li a nmu ete Ọlọrun fun majẹmu titun ṣẹ?

33 Nitorina ete Ọlọrun fun “majẹmu titun” na pẹlu Israeli ti ẹmi li a muṣẹ ninu awọn 144,000 wọnni, nitoripe majẹmu titun na li a pinnu lati mu “ijọba alufa ati orilẹ-ede mimọ?” jade, ohun kan ti majẹmu Ofin lailai ti Mose ko le mu jade. (Eksodu 19:5, 6) “Ogunlọgọ nla” ti Ifihan 7:9-17 li a ko mu wọ̀ inu majẹmu titun na, ṣugbọn loni nwọn ndarapọ pẹlu “iyoku” Israeli ti ẹmi ti o wà ninu majẹmu titun na.

34, Nibo ni awọn wọnni ti o jẹ ti “ogunlọgọ nla” ti nreti lati gbadun iye ainipẹkun, iru ijẹwọ wo ni nwọn si ṣe nipa Ọlọrun ati Ọdọ-agutan rẹ̀?

34 Nitorina “ogunlọgọ nla” ko reti lati lọ si ọrun ani lẹhin ti nwọn ba la “ipọnju nla” na ja. Awọn wọnni ti o jẹ “ogunlọgọ” nla nreti ki Ọdọ-Agutan Ọlọrun ṣe oluṣọ-agutan wọn nihin lori ilẹ aiye lẹhin “ipọnju nla” na ki o si ṣamọna wọn lọ si iye ainipẹkun ninu Paradise ori ilẹ aiye. Nwọn jẹ́wọ Ọlọrun ti mbẹ lori itẹ li ọrun gẹgẹ bi Ọba Alaṣẹ Agbaiye lori gbogbo iṣẹda. Nwọn jẹwọ Messiah na Jesu gẹgẹ bi “Ọdọ-Agutan Ọlọrun ẹniti o kó ẹṣẹ aiye lọ” nwọn si tun jẹwọ pe nwọn yio ri igbala wọn gba lati ọdọ Ọlọrun nipasẹ Ọdọ-Agutan rẹ̀ ti a ti “pa” nigbakanri, ati nipa igbagbọ ati igbọran,” nwọn ti fọ aṣọ wọn nwọn si ti sọ wọn di funfun ninu ẹjẹ Ọdọ-Agutan.”

35. (a) Nibo ninu “tempili” Ọlọrun ni nwọn ti nsin I lati igba de igba, esitiṣe? (b) Bawo ni nwọn ṣe fi iṣotitọ wọn han si Olori Alufa Ọlọrun, bawo ni Jesu si ṣe ṣapẹrẹ wọn ninu owe kan?

35 Nwọn jẹwọ kiki Oluwa Jehofah Ọba Alaṣẹ gẹgẹ bi Ọlọrun wọn. Eyiyi ṣalaye idi ti a fi ri wọn ti “nwọn si nsin i li ọsan ati li oru ninu tempili rẹ̀,” ninu àgbàlá ti ilẹ aiye ti tempili rẹ̀ nipa ti ẹmi, Ibi Mimọ Julọ ninu tempili eyiti mbẹ ninu ọrun mimọ. (Heberu 9:24) Nitorina “ogunlọgọ nla” wà timọtimọ pẹlu iyoku 144,000 Israeli ti ẹmi nisisiyi awọn ẹniti o jẹ ọba alufa lọjọ ọla eyiti majẹmu titun mu jade. Ninu ifihan iṣotitọ wọn si Jesu Kristi ọba Olori Alufa, awọn wọnni ti o jẹ “ogunlọgọ” nla jẹ olôtọ si awọn arakunrin rẹ̀ ti ẹmi ti nwọn ṣi mbẹ sibẹ lori ilẹ aiye: Nwọn nṣe gbogbo rere ti nwọn le ṣe si awọn arakunrin Kristian ti ẹmi, ani nwọn ti lẹ ndarapọ pẹlu wọn ninu wiwasu “ihinrere ijọba yi” jakejado aiye. Awọn olotọ wọnyi ni ẹgbẹ “agutan” ẹniti Jesu ṣapejuwe ninu owe rẹ̀, wipe:

“Nigbana li Ọba yio wi fun awọn ti o wà li ọwọ ọtun rẹ̀ pe, Ẹ wá, ẹnyin alabukun-fun Baba mi, ẹ jogun ijọba, ti a ti pese silẹ fun nyin lati ọjọ ìwa. Nitori ebi pa mi, ẹnyin si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin si fun mi li ohun mimu: mo jẹ alejo, ẹnyin si gbà mi si ile. Mo wà ni ihoho, ẹnyin si daṣọ bò mi: mo se aisan, ẹnyin si bojuto mi; mo: wà ninu tubu, ẹnyin si tọ̀ mi wá. Nigbana li awọn olôtọ yio dá a lohun wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, ti awa fun ọ li onjẹ? tabi tì ongbẹ gbẹ ọ, ti awa fun ọ li ohun mimu? Nigbawo li awa ri ọ li alejo, ti a gba ọ si ile? tabi ti iwọ wa ni ihoho, ti awa daṣọ bò ọ? Tabi nigbawo li awa ri ti iwọ ṣe aisan, ti a bojuto ọ? tabi ti ìwọ wa ninu tubu, ti awa si tọ̀ ọ wa? Ọba yio si dahun yio si wi fun wọn pe, Lôtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi.

“Awọn [ẹgbẹ ewurẹ] wọnyi yio kọja lọ sinu ìyà ainip̣ekun: ṣugbọn awọn olotọ si iye ainipẹkun.”—Matteu 25:34-40, 46.

36. Nigbawo ni ao ‘ke’ ẹgbẹ ewurẹ inu owe na ‘kuro,’ esitiṣe?

36 Awọn wọnni ti ko huwa gẹgẹ bi “agutan” si awọn arakunrin ti ẹmi fun Ọba Jesu Kristi ti nṣakoso nisisiyi li ao ké kuro ninu “ipọnju nla” na ti mbọ, nitoripe nwọn ko sì ninu ojurere “iru-ọmọ” “obirin” Ọlọrun li ọrun, ṣugbọn nwọn wà ni ojurere “iru-ọmọ” “ejo lailai nì,” Satani Eṣu: (Genesisi 3:15; Ifihan 12:9, 17) Nwọn juwọ silẹ fun agbara ati itọsọna “ejo lailai nì, . . . ti ntan gbogbo aiye jẹ,” nitorina nwọn yio ba ara wọn ni iha ọdọ “iru-ọmọ” Ejo na nigbati “ipọnju nla” ba bẹ́ silẹ laipẹ.

37. Igba akoko wo ni eto aiye isisiyi wà lati 1914, nitorina kini iran yi ndojukọ, gẹgẹ bi Danieli 12:1 ti wi?

37 Lati igba bibi ijọba Messiah Ọlọrun li ọrun ni ọdun 1914, ni eto awọn nkan isisiyi ti wà ni “akoko opin” rẹ̀. “Akoko opin” yi ko ni pẹ pari si “ipọnju nla” na, gẹgẹ bi Jesu Kristi ti sọtẹlẹ. Ipọnju alailẹgbẹ yi ni woli Danieli ti sọ asọtẹlẹ rẹ̀ tipẹtipẹ ki Jehofah Ọlọrun to ran Ọmọ akọbi rẹ̀ ọrun wa si aiye lati di ẹniti a npe ni Jesu. Nitorina, angeli Ọlọrun sọ ọrọ asọtẹlẹ na fun Danieli lọna bayi pe:

“Li akoko na ni Mikaeli, balogun nla nì, ti yio gbeja awọn ọmọ awọn enia rẹ̀, yio dide; akoko wahala yio si wà, iru eyi ti ko ti isi ri, lati igba ti orilẹ-ede ti wà titi fi di igba akoko yi.”—Danieli 12:1; fi we Matteu 24:21.

Iran araiye nisisiyi dojukọ “akoko wahala” na nisisiyi.

38. (a) Iru awọn oluṣe isin wo ni yio la iparun Babiloni Nla já? (b) Lati yanju ọran ariyanjiyan wo ni “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” fi gbọdọ jà?

38 Nigba “akoko wahala” na, “ipọnju nla” na, awọn agbara oṣelu ti o lodi si isin yio pa Babiloni Nla ode-oni run, eyini ni, ilẹ ọba isin eke agbaiye eyiti o bẹrẹ pẹlu Babiloni igbánì. (Genesisi 10:8-12; Ifihan 17:1 titi de 18:24) Labẹ ábò Ọlọrun, awọn memba “iyoku” Israeli ti ẹmi ati “ogunlọgọ” nla yio la iparun na ja gẹgẹ bi oluṣe isin tôtọ. (Jakobu 1:27) Ni kete lẹhin ikuna lati ọdọ awọn agbara ọta isin lati mu “isin!” mìmọ ati ailéri kuro, isin mimọ gaára na, li ori ilẹ aiye, nigbana ni “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” yio de nibiti a npè ni Har—Magedon li ede iṣapẹrẹ. (Ifihan 16:14, 16) Eṣe? Nitoripe a nilati yanju ọran ariyanjiyan agbaiye ti jijẹ ọba alaṣẹ Jehofah lori gbogbo iṣẹda jakejado aiye, eyiti iyoku na ati “ogunlọgọ” nla dimu. Yiyanju ọran ariyanjiyan yi jẹ apapọ ninu “ipinnu ataiyebaiye ti on ti pinnu ninu Kristi Jesu, Oluwa wa,” ẹniti o jẹ Olori ninu “iru-ọmọ” Ọlọrun ti a ṣeleri.”

39, 40. (a) Nibo ni idojujakọ ti ologun lori ọran ariyanjiyan na yio gbe ṣẹlẹ, tani awa si ri ti nkorajọpọ nibẹ? (b) Tani yio fihan pe on ga ju nibẹ nipasẹ iṣẹgun?

39 Jijẹ awọn ọba alaṣẹ orilẹ-ede eyiti awọn ijọba oṣelu tẹpẹlẹmọ loni, nkọlura pẹlu Jijẹ Ọba Alaṣẹ Agbaiye ti Ẹlẹda. Ikọlura ti ologun lori ọran ariyanjiyan pataki yi nsunmọ opin gẹgẹ bi “akoko opin” ti ntan lọ. Awa ha ri, loju imọlẹ awọn apẹrẹ ohun ti mbọ, awọn ọba aiye ati awọn alaṣẹ iṣelu ati ogun wọn ati awọn alatilẹhin ti a nkojọpọ si pápá ogun Har—Magedon fun jija a li ajapari? Bẹni?

40 Ṣugbọn, awa si tun ri pẹlu nipa igbagbọ Ọba awọn ọba li ọrun, Jesu Kristi, ati awọn ogun angeli rẹ̀ ti nwọn nyara kánkán lọ si pápá ogun na bi ẹnipe o ngun ẹṣin funfun. Awa le gba ọrọ Ọlọrun gbọ fun ohun ti o sọ; ogun Har—Magedon yio pari sì iṣẹgun fun awọn agbara ogun Ọlọrun Olodumare, ati iparun fun gbogbo awọn eto iṣelu atọwọda enia ati awọn ti o di ipo oyè wọn mu, awọn alatilẹhin onifẹ orilẹ-ede ẹni. Jesu Kristi ti o ti dabi Ọdọ-Agutan nigbakanri yio fi ara rẹ̀ han gẹgẹ bi Ọbà awọn ọba, nitoripe Jehofah Ọlọrun yio wà li ọwọ ọtun rẹ̀ gẹgẹ bi Jagunjagun kan lẹba Ọba ati Alufa rẹ̀ ti o dabi Melkisedeki.—Ifihan 17:12-14; 19:11-21; Orin Dafidi 110:4, 5.

41. (a) Lẹhin Har—Magedon, eṣe ti “ejo lailai nì” ko fi ni le tun jagun lodi si iyoku na ati “ogunlọgọ nla”? (b) Lọna ironu wo ni akoko ti o ṣe pataki julọ yio fi de nisisiyi fun “iru-ọmọ” “obirin” Ọlọrun?

41 Eyini ni ogogoro ologo fun ‘ègbé fun ilẹ aiye ati fun okun,’ inu eyiti “ejo lailai nì” ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀, lati igba lile wọn jade kuro li ọrun, ti ndari gbogbo araiye ti a tanjẹ si! (Ifihan 12:7-12) Pẹlu pipa gbogbo “iru-ọmọ” rẹ̀ run lori ilẹ aiye ni Har—Magedon, “ejo lailai nì” ko ni le ba “iyoku iru-ọmọ [obirin] na jagun ati “olunlọgọ nla” ti awọn ẹlẹgbẹ olujọsin Jehofah Oluwa Ọba Alaṣẹ. (Ifihan 12:13, 17) A ha nilati fi “ejo lailai nì” ati “iru-ọmọ” ẹmi eṣu rẹ̀ ti a ko le fojuri silẹ laisi ikalọwọko ni agbegbe ilẹ aiye wa eyiti a ti lé wọn ju si lati ọrun bi? Bẹkọ! Nitori nisisiyi ni akoko ti o ṣe pataki julọ de fun Jesu Kristi “iru-ọmọ” “obirin” Ọlọrun li ọrun ẹniti a ti pa ni gigisẹ nigbakanri lati ọwọ Ejo ẹlẹmi-apania na! Awọn nkan yipada, nisisiyi “iru-ọmọ!” “obirin” Ọlọrun li ọrun nilati “fọ́ ori” Ejo na, ki o si sọ on ati “iru-ọmọ” ẹmi eṣu rẹ̀ di alaisi bi ẹnipe nwọn ko waláyè tẹlẹri! Bawo?

42. (a) Bawo, nigbana, li ao ṣe fọ Ejo na ati “iru-ọmọ” rẹ̀ lori? (b) Iyipada wo ni yio ṣẹlẹ nigbana niti agbara iṣakoso li ọrun ati ẹgbẹ enia lori ilẹ aiye?

42 Nipa mimu Ejo na ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ kuro ni agbegbe ilẹ aiye ki o si ju wọn sinu “ọgbun ainisalẹ” bi igbati a fi ẹ̀wọ̀n dè e, fun ẹgbẹrun ọdun ti o tẹle e. Ifihan 20:1-3 ṣapẹrẹ eyi, ki iṣe gẹgẹ bi apakan ogun na ni Har—Magedon, ṣugbọn gẹgẹ bi ohun ti o tẹle ogun na. (Genesisi 3:15; Romu 16:20; Luku 10:18-20) Nipa bayi “ọrun” Satani ti o ti lọjọ lori lori iran enia ilẹ aiye li ao mu kuro titilai, “ọrun titun” ti MessiahỌlọrun yio mu ara rẹ̀ gborò ninu ibukun lori ẹgbẹ iran enia titun lori ilẹ aiye. Wò o nigbana bi awọn ọrọ aposteli Peteru ti ni imuṣẹ iṣẹgun, ẹniti, lẹhin ṣiṣapejuwe iparun ọrun ati aiye iṣapẹrẹ, o rọ gbogbo awọn olôtọ olujọsin Jehofah Ọlọrun nipa wiwipe: “Ṣugbọn gẹgẹ bi ileri rẹ̀, awa nreti awọn ọrun titun ati aiye titun, ninu eyiti ododo ngbe.”—2 Peteru 3: 7-13; Ifihan 20:11; 21:1; Isaiah 65:17.

[Ibeere]