Messiah “Ete Aiyeraiye” Ọlọrun
Ori 11
Messiah “Ete Aiyeraiye” Ọlọrun
AJINDE ilu kan ti o ti wà ninu iparun iku fun adọrin ọdun—li ọdun 537 B.C.E.! Ilu na ni Jerusalemu ti a ti parun lati ọwọ awọn ara Babiloni ni 607 B.C.E. Nigbati ilu mimọ yi dide lati inu ekuru, ilẹ Juda tun di atunbi, bẹni, atunbi orilẹ-ede kan, awọn enia Jehofah ti a tun mu padabọsipo. (Isaiah 66: 8) Ohun iyanu li o jẹ li oju gbogbo awọn oworan.
2. (a) Messiah ti a ṣeleri ti mbọ nilati pẹ ju aṣoju Jehofah wo ti a fi ororo yan? (b) Bawo li a ṣe mu adọrin ọdun ikolẹru ṣẹ biotilẹjẹpe Babiloni ṣubu ni 539 B.C.E.?
2 Pẹlu ajinde orilẹ-ede yi, a tun mu sọji awọn ireti fun dide Messiah na ti a ti ṣeleri. (Esekieli 37:1-14) Ani nigba adọrin ọdun na ti awọn enia ijọba Juda fi wà li oko ẹrú ni ilẹ Babiloni, akoko ti a yan fun dide Messiah na li a ti fihan fun wọn. Messiah yi nilati jẹ ẹnikan ti yio wá lẹhin Kirusi Nla, aṣẹgun Persia, nipa ẹniti a ti misi woli Isaiah lati kọwe: “Bayi ni [Jehofah] wi fun ẹni ororo [Heberu: ma-shi’ahh] rẹ̀, fun Kirusi, ẹniti mo di ọwọ ọtun rẹ̀ mu, lati ṣẹgun awọn orilẹ-ede niwaju rẹ̀; emi o si tú amure ẹ̀gbé awọn ọba, lati ṣí ilẹkun abawọle rẹ̀, ki ilẹkun ode rẹ̀ maṣe jẹ tífì.” (Isaiah 45:1) Gẹgẹ bi ẹni-ororo aṣoju Jehofah, Kirusi ti wá o si ti gba awọn ilẹkun abawọle ilu Babiloni olodi giga na kọja, o ti biṣubu o si ti pa Belṣassari, alakoso ọba nla na, ọmọ Nabonidu. Eyini ṣẹlẹ ni 539 B.C.E. Ṣugbọn Kirusi ko da awọn ọmọ Israeli igbekun nì silẹ lẹsẹkẹsẹ. O gba ipo ọba Babiloni o si di awọn Ju mu gẹgẹ bi igbekun fun nkan bi ọdun meji si i titi di 537 B.C.E. Nipa bayi awọn adọrin ọdun ni imuṣẹ!
3. Bawo li o ti pẹ to ti ilẹ Juda ti a sọdi ahoro fi pa isimi mọ?
Jeremiah 25:11. 2 Kronika 36:20, 21 si ṣe akọsilẹ eyi ninu itan, wipe: “Awọn ti o ṣiku lọwọ ida li o ké lọ si Babiloni, nibiti nwọn jẹ iranṣẹ fun u, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ titi di ijọba awọn ara Persia. Lati mu ọrọ [Jehofah] ṣẹ lati ẹnu Jeremiah wa, titi ilẹ na [ti Juda] yio fi san ọdun isimi rẹ̀; ani ni gbogbo ọjọ idahoro on nṣe isimi titi adọrin ọdun yio fi pe”—lati 607 B.C.E. si 537 B.C.E.
3 Eyiyi ri gẹgẹ bi a ti ṣe sọtẹlẹ gn ninu4, (a) Nigbawo ni Danieli ṣe iṣiro pe opin ikolẹru awọn Ju yio de? (b) Isọfunni wo ni Gabrieli fifun Danieli nipa akoko bibọ Messiah na?
4 Lara awọn Ju ti a ko ni igbekun ni Danieli woli na wà. Lati inu awọn akọsilẹ onimisi ti Jeremiah kọ, Danieli ko reti pe idande kuro ’ninu igbekun yio de fun awọn Ju bikoṣe li opin adọrin ọdun ti Jerusalemu fi wà li ahoro ni pipa ọjọ isimi mọ. (Danieli 9:1, 2) Nitorina nigba ọdun ekini iṣakoso titun ti Medo-Persia lori Ilẹ-ọba Babiloni, Danieli gbadura nipa ọran na. Nigbana ni Gabrieli angeli Jehofah fun Danieli ni awọn ọrọ wọnyi nipa akoko fun Messiah lati wa:
“Adọrin (ọdun-) ọsẹ li a pinnu sori awọn enia yẹ, ati sori ilu mimọ rẹ, lati ṣe ipari irekọja, ati lati fi edidi dí ẹṣẹ, ati lati ṣe ilaja fun aiṣedede ati lati mu ododo ainipẹkun wa ati lati ṣe edidi iran ati woli, ati lati fi ororo yan Ẹni-mimọ julọ nì.
“Nitorina ki iwọ ki o mọ, ki o si yé ọ, pe lati ijadelọ ọrọ na lati tún Jerusalemu se, ati lati tun u kọ, titi de igba ọmọ-alade Ẹni-ororo na, yio jẹ (ọdun) ọsẹ meje, ati (ọdun) ọsẹ mejilelọgọta: a o tun igboro rẹ̀ ṣe, a o mọ odi rẹ̀, ṣugbọn nigba wahala.
“Lẹhin (ọdun-) ọsẹ mejilelọgọta na li a o ké Ẹni-ororo na kuro, ki yio si si ẹnikan fun u, ati awọn enia ọmọ-alade kan ti yio wá ni yio pa ilu na ati ibi-mimọ run; opin ẹniti yio ba ikún omi de; ogun yio si má, jà titi de opin; idahoro ni a si pinnu.
“On o si fi idi majẹmu kan mulẹ fun ọpọlọpọ niwọn (ọdun-) ọsẹ kan: ati lárin [abọ̀] (ọdun-) ọsẹ na ni yio mu ki a dẹkun ẹbọ, ati Ọrẹ-ẹbọ; asọnidahoro yio si wà lori ìyé irira, titi idajọ ti a pinnu yio fi tú dà sori asọnidahoro.”—Danieli 9:24-27, Zunz; tun wo Moffatt pẹlu.
“OWURỌ” “ỌJỌ” IṢẸDA KEJE BẸRẸ, NI NKAN IBI 526 B.C.E.
5. Bawo li a ṣe ṣe iṣiro na nigbati ’’awọn ọsẹ ọdun” meje pẹlu mejilelọgọta yio dopin?
5 Idaji ekini tabi “aṣalẹ” akoko “ọjọ” iṣẹda ekeje npari lọ nisisiyi, 3,500 ọdun lati igba didá. Adamu ati Efa. Owurọ ’fọjọ” iṣẹda yi yio bẹrẹ ni nkan bi 526 B.C.E. Lati igba na lọ awọn nkan nilati danmọran niti ete Ọlọrun ati fun awọn enia Rẹ̀. Gẹgẹ bi asọtẹlẹ Danieli ti wi, lati inu ami kan ninu ṣiṣe atunkọ ilu Jerusalemu ti a ji dide adọrin “(ọdun-) ọsẹ” tabi “awọn ọsẹ ọdun” (ti o jẹ apapọ 490 ọdun) yio ni nkankan iṣe, “(Ọdun-) ọsẹ meje” pẹlu “(ọdun-) ọsẹ mejilelọjọta” yio nasẹ fun apapọ 483 ọdun titi dide Ẹni-ororo (Heberu: Ma-shi’ahh) na. Bi a ba kà a lati igbati gomina Ju na Nehemiah tun awọn odi Jerusalemu ké, awọn ’’’ọsẹ ọdun” mọkandinladọrin wọnyi yio dopin ni idaji ọgọrun ọdun ekini ti Sanmani Igba Tiwa. Bi a ba kà a lati igba ogun ọdun Ọba Artasasta (455 B.C.E.), ọdun na ti Nehemiah tún awọn odi wọnni kẹ, 483 ọdun na yio pari ni ọdun 29 ti Sanmani Igba Tiwa. (Nehemiah 2:1-18) Eyini jẹ nkan bi ọdun mọkanlelogoji ṣaju iparun Jerusalemu lẹkeji, li akoko yi lati. ọwọ awọn ara Romu. Ohun kan ha ṣẹlẹ ninu itan ni 29 C.E. bi?
6. Bawo li a ṣe bì Ilẹ Ọba Persia ṣubu, bawo si ni Aleksandria, Egipti, ṣe wa ko ipa kan ninu igbesi aiye awọn Ju?
6 Ọgọrun ọdun ekini B.C.E. ati ọgọrun ọdun ekini B.C.E, jẹ awọn ọdun ti o lekoko fun awọn ọmọ Israeli ni Palestine. Ni ọgọrun ọdun kẹrin B.C.E. iṣakoso awọn ọmọ Israeli tabi Ju ti a dá pada si ilu wọn rekọja lati ọwọ awọn ọba nla Persia si ọwọ Ilẹ Ọba Greece, nitori awọn iṣẹgun Aleksanderu Nla ara Makedonia na. Li ọdun 332 B.C.E. o gba iṣakoso Palestine o si fi Jerusalemu silẹ laifi ọwọ kàn a. Nigbana li o bì ọba nla Persia ṣubu o si gbe Agbara Aiye Griki kalẹ, ikarun ninu itan Bibeli. Li ọdun kanna Aleksanderu paṣẹ pe ki a tún ilu Aleksandria kọ ni Egipti ti a ti ṣẹgun. Eyiyi di ilu alásiki, ọpọ iye awọn Ju li o si dagba nibẹ. Awọn wọnyi di ẹniti nsọ ede Griki ti o wọpọ, eyiti ti di ede kan nisisiyi ti a mò li agbaiye ti a si nlo nitori awọn iṣẹgun Aleksanderu. Nwọn si tun nfẹ imọ Bibeli pẹlu.
7. Bawo li a ṣe pese Septuagint Version li ede Griki, bawo li o si ti kà ninu Danieli 9:25, 26?
7 Nitorina, nigba ọgọrun ọdun ti o tele e, ni nkan bi 280 B.C.E., nwọn bẹrẹ iṣẹ titumọ Iwe Mimọ wọn ti a misi, lati Genesisi titi de Malaki, sinu ede Griki wọn ti gbogbo enia nsọ. A pari rẹ̀ ni nkan bi ọgọrun ọdun ekini B.C.E. o si di ohun ti a npe ni “The Greek Septuagint Version.” Loju lilo ti ọpọ enia nlò ede Griki na ti o wọpọ, pápá nigba awọn ọgọrẹrun ọdun ekini nigba iṣakoso Ilẹ Ọba Romu, itumọ yi lati ọwọ awọn Ju ti ngbe Aleksandria, li a le lo ni agbaiye. O fi itumọ Bibeli li ede Heberu han li otitọ. Fun apẹrẹ, itumọ Danieli 9:25, 26 li ede Griki nipa Messiah (Ma-shi’ahh) na gẹgẹ bi itumọ ede Gẹsi Bagster kà bayi pe:
Iwọ yio si mò yio si yé ọ pe lati ijadelọ aṣẹ na fun idahun ati fun atunkọ Jerusalemu titi di igba Kristi ọmọ-alade na yio jẹ ọsẹ meje, ati ọsẹ mejilelọgọta: nigbana ni akoko na yio de, a o si tun opopo ọna kẹ, ati odi, akoko na yio si pari. Lẹhin ọsẹ mejilelọgọta, ẹni ororo na li a o parun, ko si ni si idajọ ninu rẹ̀: . . .”
8. (a) Bawo ni Jerusalemu ṣe bọ sabẹ iṣakoso Romu ti a si pa a run lẹhinna? (b) Bawo li o ti pẹ to ti awọn Ju ko fi ni tempili ni Jerusalemu tabi ti nwọn iko tẹwọgba wolo kan lati ọdọ Ọlọrun?
8 Griki ti o wọpọ na mba a lọ lati di ede agbaiye igbánì na ani pápá nigbati Agbara Aiye Griki ṣubu niwaju Agbara Aiye Romu li ọgọrun ọdun ekini, B.C.E. Apa kan ninu awọn oludije ara Maccabe fun agbara ní Jerusalemu bẹ̀bẹ̀ fun iranlọwọ lati Romu lodi si apa keji, nitorina li ọdun 63 B.C.E. Pompey ọgagun Romu kọlu o si gba iṣakoso Jerusalemu, Palestine si bọ́ si abẹ iṣakoso Romu. Ni 40 B.C.E. awọn Ju tun gba ipo ọba pada. Ṣugbọn, ni 37 B.C.E. Herodu Nla, atọmọdọmọ Esau tabi Edomu, kọlu Jerusalemu o si ṣẹgun rẹ̀ o si ṣakoso bi ọba, gẹgẹ bi ẹniti Romu yan. Ni ọgọrun ọdun ekini C.E., awọn Ju tun ṣọtẹ si Romu,
ni 66 C.E. ṣugbọn ominira wọn alakoko kukuru li a fi opin si ni 70 C.E. nipasẹ iparun Jerusalemu ati tempili. rẹ̀ ologo ti Herodu Nla ṣe atunlksọ rẹ̀. Lati igba na, tabi fun eyiti o ju ọgọrun ọdun lọna mọkandinlogun lọ nisisiyi, awọn Ju koiti ní tempili ni Jerusalemu, ani lati igbati a ti gbe Republic of Israel kalẹ ni 1948 C.E. Yatọ si eyini, awọn Israeli ode-oni ko gba pe woli kankan wá lati ọdọ Ọlọrun lati igba aiye Malaki ti ọgọrun ọdun karun B.C.E., tabi eyiti o ju 2,400 ọdun lọ sẹhin. Eyini ko ha ṣajeji bi? Kini ṣẹlẹ?IMUṢẸ ASỌTẸLẸ BIBELI ṢALAYE AWỌN ỌRAN
9. Nigbati a tun ṣe igbekalẹ Jerusalemu ni 537 B.C.E., ilu Pataki miran wo li a tun mu padabọ sipo?
9 Nigbati a ṣe atungbekalẹ Jerusalemu igbánì ni 537 B.C.E., ilu miran li a tun mu padabọ sipo ni ilẹ Juda—Betlehemu. Ninu Nehemiah 7:5-26, gomina Jerusalemu sọrọ nipa iyoku awọn Ju ti o pada si ilu wọn ni 537 B.C.E., wipe:
Mo si ri iwe idile awọn ti o kẹ goke wa, mo ri pe, a kọ ọ sinu rẹ̀:
Wọnyi ni awọn ọmọ igberiko, ti o goke wá lati igbekun ninu awọn ti a ti ko lọ, ti Nebukadnesari ọba Babiloni ti ké lọ, ti nwọn tun pada wá si Jerusalemu, ati si Juda, olukuluku si ilu rẹ̀. Awọn ti o ba Serubbabeli wá, Jeṣua [Griki Septuagint: Jesu], Nehemiah, . . . Iye awọn ọkunrin enia Israeli li eyi: . . . Awọn ọkunrin Betlehemu ati Netofa, ọgọsan o le mẹjọ . . .”—Tun wo Esra 2:21 pẹlu.
10. (a) Nipa bayi Betlehemu Wa li arọwọto fun imuṣẹ asọtẹlẹ wo? (b) Eṣe ti ko fi gbọdọ jẹ alaiṣe-gbagbọ pe ibimọ ti a ṣeleri nibẹ ni awọn angeli nilati kede rẹ̀?
10 Nipa bayi ilu Betlehemu, “ilu Dafidi?” tun waláyẹ̀ lẹkan si i, ninu eyiti o ṣéṣe fun asọtẹlẹ Messiah ti Mika 5:1 (Leeser 5:2, Greek Septuagint) lati ni imuṣẹ. Niwọnbi gbogbo iwaláyé enia olominira ti bẹrẹ lati ọdọ Kaini ati Abeli titi lọ lati igba ibimọ, asọtẹlẹ Mika mu ki a fojusọna fun ibimọ kan ninu Betlehemu ti a tunkọ. Eyiyi nilati jẹ ibimọ kan ti a sọtẹlẹ. Nisisiyi, nigbati Isaaki, ọmọ Abrahamu ati Sarah, di ẹniti a nilati bi lọna iyanu, awọn angeli mẹta lati ọdọ Ọlọrun bẹ̀ wọn wò nwọn si kede ibimọ ti mbọ li ọdun ti o tẹle e, aṣaju angeli na wipe: “Ohun kan ha ṣoro ju fun [Jehofah]?” (Genesisi 18:1-14) Ọgọrẹrun ọdun lẹhinna, nigbati ọmọbirin Israeli kan ti o yàgàn titi di igba na yio fi bi Samsoni, ọkunrin ti o ti lagbara julọ lori ilẹ aiye, angeli Ọlọrun farahan lakọkọ fun ẹniti yio jẹ iya rẹ̀ lọjọ iwaju ati lẹhinna fun on ati ọkọ rẹ̀ alailọmọ, lati kede ibimọ onidajọ olokiki kan ti mbọ ni Israeli. (Awọn Onidajọ 13:1-20) Ẹmikẹni ha le ro pe o ṣajeji, ko ṣe igbagbọ, pe ohun ti yio jẹ ibimọ gigajulọ ninu gbogbo ibimọ awọn enia, bibi Messiah na lọna iyanu, li ao kede rẹ̀ fun awọn.enia nipasẹ awọn angeli ọrun?
11. Gẹgẹ bi Genesisi 3:15 ti wi, ẹni na ti a yan fun iṣẹ Messiah ori ilẹ aiye li a nilati mu wa lati ibo?
11 Gẹgẹ bi asọtẹlẹ Jehofah ninu Genesisi 3:15 ti wi, “iru-ọmọ” ti yio fọ́ ori Ejo na pa nilati wá lati ọdọ “obirin” Ọlọrun li ọrun, eyini ni, eto mimọ ti ọrun ti “awọn ọmọ Ọlọrun toôtọ” ti o dabi aya. Lati inu eto na Ọlọrun le yàn ọmọ ẹmi pataki kan fun iṣẹ Messiah lori ilẹ aiye.
12. Awọn ibere wo li o dide nisisiyi nipa ọmọbirin na ti yio jẹ iya enia fun ’Messiah na, ati nipa ọkọ rẹ̀ pẹlu?
12 Kini orukọ ọmọ na ti a ṣe ojurere si yi? Ibere kan ti o dumọni! Ṣugbọn fun bibi ọmọ ti a yàn yi, ẹniti a nilati bi sinu idile enia ni Betlehemu ni ilẹ Juda, a nfẹ enia kan ti yio jẹ iya. Ki iṣe kiki pe on nilati jẹ ti ẹya Juda nikan ni, ṣugbọn on nilati jẹ atọmọdọmọ Ọba Dafidi ki on si le tipa bayi ta atare ẹtọ nipa ẹda si ijọba Dafidi. Ọmọbirin wo ẹniti ilu ibi rẹ̀ jẹ Betlehemu ni Juda li o kájú awọn ohun ti a mbere na? Nipa ti ọkọ ti o jẹ enia nkọ fun u, ki o si jẹ ti idile ọba Dafidi? A ha ni ikede kan lati ẹnu angeli nipa bibi ọmọ kan ti o tobiju Isaaki bi? Itan akọsilẹ, gẹgẹ bi awọn ọrẹ ọmọbirin na ti ṣe kọ ọ silẹ, dahun awọn ibere pataki wọnyi.
13, 14. (a) Nibo li a ti ri wundia Ju ti o ba a mu gẹ? (b) Lẹhin ti o ti kí i, kini angeli Gabrieli wi?
13 Akoko na nisisiyi dari opin ọgọrun ọdun ekini ṣáju Sanmani Igba Tiwa. Herodu Nla, ọmọ Antipater II,
ṣi jẹ ọba ni Jerusalemu sibẹ. Heli, ọkunrin kan ni ila idile Dafidi, ti ké kuro lati Betlehemu ni agbegbe Judea lọ si ariwa Nasareti ni agbegbe Galili, Nibẹ ni ọmọbirin rẹ̀, ti a npe ni Miriamu (Heberu) tabi Mariamu (pẹlupẹlu Maria) li ede Griki, ti dagba di ẹniti o le lọkọ. O di ẹniti a fẹ sọna lati ṣe aya ọkunrin kan ni ila idile ọba Dafidi, ti a npe ni Josefu, gbẹnagbẹna kan ni Nasareti ṣugbọn ti on tun jẹ ọmọ ilu Betlehemu. Eyiyi sọ ọ di ọranyan fun u lati pa wundia rẹ̀ mọ. Ṣugbọn ọpọ oṣu ṣáju alẹ igbeyawo, ohun iyanu kan ṣẹlẹ. Angeli kan, ẹniti o pe ara rẹ̀ ni Gabrieli, farahan si Maria tabi Mary. Lẹhin ìkíni o wipe:14 “Ma bẹru, Maria: nitori iwọ ti ri ojurere lọdọ Ọlọrun. Sa si kiyesi i, iwọ o loyun ninu rẹ, iwọ o si bí ọmọkunrin kan, iwọ o si pẹ̀ orukọ rẹ̀ ni JESU [Heberu: Jeshua]. On o pò, Ọmọ Ọga-ogo julọ li a o si ma pẹ e: IJehofahJ Ọlọrun yio si fi itẹ Dafidi baba rẹ̀ fun u. Yio si jọba ni ile Jakobu titi aiye; ijọba rẹ̀ ki yio si ni ipẹkun.”—Luku 1:26-33.
15. (a) Majẹmu wo li a ba Dafidi da ti ao muṣẹ ninu ọmọ Maria? (b) Jijẹ ti on jẹ “Ọmọ Ọga-ogo julọ” tumọsi kini?
15 Gẹgẹ bi ọrọ ti angeli na sọ, ọmọ Maria gan ni yio jẹ Messiah na ti a ṣeleri. A nilati pé e li orukọ kanna gẹgẹ bi ti olori alufa ti o padabọ pẹlu Serubbabeli lati. Babiloni ni 537 B.C.E., eyini ni, Jeshua, tabi, ni Griki, Jesu. Nitori bibi nipasẹ Maria a nilati pe e ni “ọmọ Dafidi baba rẹ̀.” Nitorina, Jehofah Ọlọrun yio fun u ni itẹ tabi ijoko Ọba Dafidi. Gẹgẹ bi o ti ri fun Dafidi, iṣakoso ọba rẹ̀ yio wà lori “ile Jakobu,” eyini ni, lori gbogbo Israeli. Niwọnbi iṣakoso ọba rẹ̀ yio ti wà titi lai ti ko si ni si ’opin ijọba rẹ̀,’ eyiyi tumọsi pe Jehofah Ọlọrun yio mu ṣẹ ninu rẹ̀ majẹmu na ti Jehofah ti ba Dafidi dá fun ijọba ainipẹkun kan. Nipa bayi on kò ni wá arọpo kankan. (2 Samueli 7:11-16) Ṣugbọn bawo, ésitiṣe, ti a fi nilati pé e ni ’’Ọmọ Ọga-ogo Julọ”? Eni yi ko ni jẹ Ọga-ogo Julọ funrarẹ̀, ẹniti iṣe Jehofah, ṣugbọn on yio jẹ Ọmọ kan fun Ẹni Gigajulọ na; sibẹ, bawo?
16. Ni idahun si ibere Maria nipa bi eyiyi ti ṣe le ṣẹlẹ, kini Gabrieli wi?
16 Maria funrarẹ̀ bere nipa eyi, wipe: “Eyi yio ha Luku 1:34-37.
ti ṣe ri bẹ, nigbati emi ko ti mẹ ọkunrin?” Gabrieli dahun pe: “Ẹmi mimọ yio tò 6 wá, ati agbara Ọga-ogo yio ṣiji bò ọ: nitorina ohun mimọ ti a o ti inu rẹ bi, Ọmọ Ọlọrun li ao má pẹ e. Si kiyesi i, Elisabeti ibatan rẹ, on pẹlu si loyun ọmọkunrin kan li ogbologbo rẹ̀: eyi si li oṣu kẹfa fun ẹniti a npe li àgàn. Nitori ko si ohun ti Ọlọrun ko le ṣe.”—17. Nigbawo ni iloyun lọna iyanu ninu Maria ṣẹlẹ?
17 Ohun ti a kede nibẹ fun Maria ha di ohun ti ko le ṣẹṣe? Wundia ọmọbirin Ju yi jẹ apẹrẹ kan fun wa li oni ni gbigbagbọ pe ko ni di ohun ti ko ṣéṣe fun Ọlọrun Ọga-ogo. Nitorina o dá Gabrieli angeli na lohun: ’’Wo ọmọ-ọdọ IJehofahT; ki o ri fun yhi gẹgẹ bi ọrọ rẹ.” (Luku 1:38) Laisi aniani, nigbati Maria tẹwọgba ifẹ Ọlọrun fun u, oyun ṣẹlẹ ninu rẹ̀, sibẹ o jẹ wundia. Ẹmi mimọ bà le e, agbara Ọlọrun Ọga-ogo Julọ si ṣiji bò o. Nipa bẹ bawo li a ṣe mu iloyun jade lọna iyanu?
18, 19. (a) Eṣe, nigbati Maria loyun, ti ki iṣe fifun ẹda titun kan patapata ni ibẹrẹ laisi ipilẹ kankan? .(b) Ọmọ tani a le fi pẹlu ẹtọ pẹ̀ e?
18 Ninu ọran yi a ko mu ẹda titun kan patapata jade ilaisi iriri iṣáju eyikeyi tabi itan, gẹgẹ bi o ti ri niti ọran iloyun enia lasan nipasẹ baba ti o jẹ enia. “Obirin” Ọlọrun li ọrun, eto Ọlọrun li ọrun ti o dabi obirin, li a nilati fi sọkan. Nitotọ lati ọdọ rẹ̀ ni “iru-ọmọ” ti a mẹnukan ninu Genesisi 3:15 ti wá. Nitorina o nilati pese ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀ ti ẹmi fun iṣẹ ori ilẹ aiye yi, fun “iru-ọmọ” na lati di ẹniti a pa ni gigisẹ lati ọdọ Ejo na.
19 Eyiyi ko tumọsi pe, fun Maria ọmọbirin wundia Ju na lati loyun, ọkan ninu awọn ọmọ ẹmi Ọlọrun li ọrun li a nilati ran wá lati fà wọ inu ile-ọmọ tabi ẹyin-ọmọ ti mbẹ lara Maria ki o si sọ ọ di nla. Iru nkan bẹ ko lọgbọn ninu, ko si dúngbQ6! Kakabẹ, Ọlọrun Olodumare, Baba ọrun, nipasẹ ẹmi mimọ rẹ̀, ta àtaré agbara iwaláyé ọmọ rẹ̀ ọrun ti o ti yan lati ilẹ ọba ẹmi sinu ẹyin ọmọ ti mbẹ ninu ara Maria o si mm u dagba. Li ọna bayi Maria loyun, ọmọ ti o si loyun ninu rẹ̀ jẹ “mimọ.” Nitôtọ ohun ti Gabrieli pe e li o jẹ, ’Ọmọ Ọga-ogo Julọ.”—Luku 1:32.
Pg 13520 Ṣugbọn, tani ọmọ na ẹniti Ọlọrun yan lati di ẹniti a bi gẹgẹ bi ẹda enia pipe? Ki iṣe angeli Gabrieli, nitoripe on li ẹniti o parada di enia ti o si farahan Maria lati kede fun u nipa dídi iya-ọmọ na. Iwe Mimọ fihan pe ẹni na li ẹniti angeli kan, nigbati o mba Danieli sọrọ pe ni “balogun nyin,” “balogun nla nì, ti yio gbeja awọn ọmọ awọn enia rẹ̀,” eyini ni, Mikaeli. (Danieli 10:21; 12:1) On ti nṣiṣẹ gẹgẹ bi angeli balogun olutọju fun orilẹ-ede Israeli, laisi aniani on si li angeli na ti o fi ara rẹ̀ han fun Mose ninu ìgbé ti njo lẹba Oke Horebu ni ọgọrun ọdun kẹrindinlogun B.C.E. lọhun. A ti pẹ e pẹlu ẹtọ gẹgẹ bi Mikaeli olori ogun. * Mimu ti a mu agbara ìiwaláyò yẹ̀ wá sinu ile ẹyin ọmọ Maria nipasẹ agbara Ọlọrun Olodumare eyiti o ṣiji bo Maria tumọsi pe on, Mikaeli, li a ko ri li ọrun. Nipa bibi ti Maria ọmọbirin wundia. Ju na bi i gẹgẹ bi enia, on nilati di enia ọkàn kan. Eyiyi mu ki o wà li arọwọto fun imuṣẹ Isaiah 53:10 nipa “iranṣẹ” Jehofah “ti njiya”:
20. (a) Ewo ninu ọmọ eto Ọlọrun li ọrun li a yan? (b) Bawo li o ṣe wà li arọwọto fun imuṣẹ Isaiah 53:10?
Sibẹ o wu OLUWA lati fi àrùn pa a kú; lati ri bi ọkàn rẹ̀ yio pese ara rẹ̀ fun irubọ-ẹṣẹ, ki on ba le ri iru-ọmọ rẹ̀, mu ọjọ rẹ̀ gun, ati pe ki ete OLUWA ba le gẹ lati ọwọ rẹ̀.”—JPS); tun wo Zunz pẹlu.
AWỌN ẸLẸRI TI BIBI LỌNA IYANU NA ṢOJU RẸ̀
21. Bawo li a ṣe ṣalaye oyun Maria fun Josefu, kini si ṣẹlẹ lẹhinna?
21 Laipẹ oyun iyanu ti wundia ọmọbirin Ju na yún di ohun ti o han gbangba si awọn ẹlomiran ni Nasareti. Afẹsọna Maria wadi rẹ̀ o si dámu rẹ̀ gidigidi. A ko le dẹbi oyun rẹ̀ fun u. Ero awọn Ju lọna ti ko ṣe pataki ni Nasareti nibẹ yio mu iyemeji wá nipa oyun Maria lọna iyanu; awọn olofintoto Ju olurọmọ Ofin Mose yio dẹbi fun u lati di ẹniti a sọ li okuta pa gẹgẹ bi panṣaga ti o ṣeke si adehun igbeyawo rẹ̀ pẹlu Josefu.
Tani le ṣe iranlọwọ fun Maria ki o si gbà on ati ọmọ rẹ̀ ti a koiti bi là kuro ninu iku nipa isọlokutapa? Tani le mu awọn nkan ṣe kedere fun Josefu? Fetisile:“Li akoko ti a fẹ Maria iya rẹ̀ fun Josefu, ki nwọn to pade, a ri i, o loyun lati ọwọ ẹmi mimọ wa. Josefu ọkọ rẹ̀, ti iṣe olôtọ enia, ko si fẹ dojuti i ni gbangba, o fẹ ikọ ọ silẹ ni ikọkọ, Ṣugbọn nigbati o nrò nkan wọnyi, wò o, angeli IJehofahJ yọ si i li oju àlá, o wipe, Josefu, iwọ ọmọ Dafidi, má foiya lati mu Maria aya rẹ si ọdọ; nitori eyi ti o yún ninu rẹ̀, lati ọwọ ẹmi mimọ ni. Yio si bi ọmọkunrin kan, Jesu [Heberu: Jeshua] ni ìwọ o pé orukọ rẹ̀: nitori on ni yio gba awọn enia rẹ̀ là kuro ninu ẹṣẹ wọn.
“Gbogbo eyi si ṣẹ, ki eyi ti a ti sọ lati ọdọ [Jehofah] wa li ẹnu woli ki o le ṣẹ pe, Kiyesi i wundia [gẹgẹbi Septuagint ti Griki ti wi] kan yio loyun, yio si bi ọmọkunrin kan, Nwọn o si má pe orukọ rẹ̀ ni Emmmanueli, Itumọ eyi ti iṣe, Ọlọrun wà pẹlu wa.
“Nigbati Josefu dide ninu orun rẹ̀, o ṣe bi angeli [Jehofah] ti wi fun u, o si mu aya rẹ̀ si ọdọ. On ko si mò ọ titi o fi bi akọbi rẹ̀ ọmọkunrin, O si pe orukọ rẹ̀ ni Jesu [Jeshua].”—Matteu 1:18-25.
22. (a) Gabrieli, ni biba Maria sọrọ, tẹnumọ apa wo nipa Messiah ọmọ rẹ̀? (b) Angeli na tẹnumọ apa mirán wo nipa ọmọ Maria fun Josefu?
22 Nipa ifiwera ohun ti Gabrieli sọ fun Maria ati ohun ti angeli na li oju àlá sọ fun Josefu, Gabrieli gbe itẹnumọ ti o gaju le ori iṣẹ ti Messiah na yio ṣe gẹgẹ bi Ọba kan ti o wá lati ọdọ Dafidi lati le mu majẹmu Jehofah ṣẹ pẹlu Dafidi fun ijọba ainipẹkun kan. Angeli na ti o farahan fun Josefu gbe itẹnumọ na kà ori iṣẹ Messiah na gẹgẹ bi alufa kan, gẹgẹ bi olù-ru ẹṣẹ kan ati olùmú ẹṣẹ kuro. Angeli yi sọrọ lori orukọ ti a nilati fifun Messiah na, orukọ na eyiti, li ede Heberu, o tumọsi “Igbala Jehofah.” Messiah na yio de oju ila orukọ rẹ̀ funrarẹ̀ niti pe on yio “gba awọn enia rẹ̀ la kuro ninu ẹṣẹ wọn.” Eyiyi ṣe dede pẹlu otitọ na pe Messiah na, Atọmọdọmọ Dafidi, nilati jẹ ’’alufa titi lai nipa ẹṣẹ ti Melkisedeki.”—Orin Dafidi 110:1-4.
23. Bawo li o ṣe jẹ ti bibi Jesu ko. ṣẹlẹ ni Nasareti?
23 Ibimọ na ha ṣẹlẹ ni Nasareti lẹhinti Josefu mu Maria lọ si ile rẹ̀ nibẹ? Bẹkọ, ki iṣe gẹgẹ bi akọsilẹ ti a misi ti wi. Ibimọ na ṣẹlẹ ninu ilu Dafidi, Betlehemu ti Juda. Bawo ni? Aṣẹ ọba nla kan lati Romu ṣiṣẹ fun imuṣẹ Mika 5:2, nipa ibiti ao bi Messiah na si. Akọsilẹ na ni yi nihin:
“O si ṣe li ọjọ wọnni, aṣẹ ti ọdọ Kesari Aungustu jade wá pe, ki a kọ orukọ gbogbo aiye sinu iwe. (Eyi ni ikọsinu-iwe ikini ti a ṣe nigbati Kireniu fi jẹ Balẹ Siria.) Gbogbo awọn enia si lọ lati kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe, olukuluku si ilu ara, rẹ̀. Josefu pẹlu si goke lati Nasareti ilu Galili lọ, si ilu Dafidi ni Judea, ti a npẹ̀ ni Betlehemu ; nitoriti iran ati ìdile Dafidi ni iṣe, lati kọ orukọ rẹ̀, pẹlu Maria aya yẹ̀ afẹsọna, ti o tobi fun oyun. O si ge, nigbati nwọn wà nibẹ, ọjọ rẹ̀ pé ti on o bí. O si bí akọbi rẹ̀ ọmọkunrin, o si fi ẹjá wé e, o si tẹ́ ẹ sinu ibujẹ ẹran; nitoriti àyò kò si fun wọn ninu ile ero.”—Luku 2 :1-7.
24, 25. Bawo li a ṣe ṣiro ọjọ ti o ṣéṣe ki a bi Jesu?
24 Oṣu ati ọjọ ibimọ na li a ko funni, ani gẹgẹ bi a ko ti má nsọ ọjọ ibi awọn enia Ọlọrun rara ninu Bibeli Mimọ.
25 Pẹlu idi rere a le sọ, biotiwukiori pe, Jesu akọbi ọmọkunrin Maria li a ko bi li ọjọ eke ti December 25 bẹni ki si iṣe li akoko otutu ajọdun Hhamukkah (Iyasimimọ), eyiti o bẹrẹ ni Ọjọ 25 oṣu oṣupa Kislev. (Johannu 10:22) Gẹgẹ bi awọn iṣiro ti a gbe ka ori Danieli 9:24-27 ti wi nipa ifarahan, iṣẹ larin awọn enia ati kike Messiah na kuro, a bi Jesu ni nkan bi ọjọ 14 oṣu oṣupa na Tishri. Eyiyi jẹ ọjọ kan ṣaju ibẹrẹ ase ọlọsẹ kan ti Sukkotu (Awọn Agọ), ni akoko ase eyiti awọn Ju ngbe lẹhin ode ile ninu awọn agọ ti awọn oluṣọ agutan yio si wà ninu pápá ti nwọn nṣé awọn agbo ẹran wọn nigba awọn ìṣò oru. (Lefitiku 23:34-43; Numeri 29:12-38; Deuteronomi 16:13-16) Niwọnbi Jesu ti gbe li aiye fun ọdun mẹtalelọgbọn ati àbẹ̀ ti o si kú ni ọjọ Irekọja ti 33 C.E., tabi ni Nisani 14 ọdun na, eyiyi fi ọjọ ìbí rẹ̀ si ibẹrẹ ikore ọdun 2 B.C.E., tabi ni nkan bi Tishiri 14 ọdun na.
26. Tani a ran angeli Ọlọrun si lati kede bibi Jesu, pẹlu ohun miran wo lati ọrun ti o ba a rin?
26 Nitoripe eyi jẹ bibi Messiah na ti a ti nfojusọna fun tipẹtipẹ, o ṣe pataki ju lati jẹki o kọja lọ laisi awọn ẹlẹri ti o ṣẹlẹ loju rẹ̀. Ọlọrun ri si eyini nipa riran angeli yẹ̀ lati kede ibimọ wundia na lọna iyanu. Ṣugbọn fun tani? Thaṣe fun Herodu Nla ninu afin ọba rẹ̀ ni nkan bi ibusọ mẹfa si ariwa ni Jerusalemu? Tabi fun alakoso tempili, Olori Alufa Joasari, ẹniti Ọba Herodu yan? Bẹkọ rara. Pẹlu abò fun Jesu ọmọ titun ti a ṣẹṣẹ bi na lọkan, Jehofah rán angeli rẹ̀ si awọn enia ti nṣe iṣẹ na ti Dafidi nṣe nigba ewe, nibẹ ninu pápá nitosi Betlehemu. On ko mu ki ohun ti a fi ẹnu lasan pe ni “Irawọ Betlehemu” ki o farahan fun gbogbo emúo, lati ri. A kà pe:
“Awọn oluṣọ-agutan mbẹ ni ilu na, nwọn nṣọ agbo agutan wọn li oru ni pápá ti nwọn ngbe. Sa si kiyesi i, angeli [Jehofah] na yọ si wọn, ogo [Jehofah] si ràn yí wọn ká; ẹ̀rù si bà wọn gidi-gidi. Angeli na si wi fun wọn pe, Má bẹru: sawo o, mo mu ihinrere ayọ nla fun nyin wá, ti yio gẹ ti enia gbogbo. Nitori a bi Olugbala fun nyin loni ni ilu Dafidi, ti iṣe Kristi Oluwa. Eyi ni yio si ṣe ami fun nyin; ẹnyin o ri ọmọ-ọwọ ti a fi ọja wé, o dubulẹ ni ibujẹ ẹran. Ọpọlọpọ ogun ọrun si yọ si angeli na li ojiji, nwọn nyìn Ọlọrun wipe, Ogo ni fun Ọlọrun loke ọrun, ati li aiye alafia, ifẹ inu rere si enia.”—Luku 2:8-14.
27. Ede wo ni angeli na lo fun Jesu ọmọ ti a ṣẹṣẹ bi na, bawo ni nwọn si ṣe ba a mu rẹgi?
27 Angeli na pe ọmọ titun na ti mbẹ ni ibujẹ ẹran Betlehemu ni “Olugbala,” eyiti o jẹ ọkan ninu awọn idi ti a fi npe orukọ rẹ̀ ni Jeshua tabi Jesu, ti o tumọsi ”Igbala Jehofah.” Ọmọ yi pẹlu nilati di Ẹni ororo Jehofah, tabi Messiah tabi Kristi (Griki). O tun nilati jẹ “Oluwa,” Ẹni na ti Ọba Dafidi pápá nigbati o nsọrọ lọna asọtẹlẹ labẹ imisi pẹ̀ ni “Oluwa mi.”—Orin Dafidi 110:1.
27 Afi Ọlọrun Olodumare nikan, nipa iṣẹ iyanu, li o le pese ọmọ kan bẹ pẹlu iru iṣẹ kan gẹgẹ bi Messiah.
Bawo li o ti jẹ iyalẹnu to, nigbana, pe “ọpọlọpọ ogun ọrun” si yọ si angeli na nwọn si darapọ ni kikọrin ogo si Ọlọrun! Ibimọ ti o yanilẹnu julọ ninu gbogbo ibimọ enia yi jẹ ifihan onifẹ ojurere Rẹ̀ si gbogbo enia ti On tẹwọgba. Iru awọn enia bẹ ti o ni ojurere Ọlọrun le wà li alafia li ọkan ati iye. Sibẹ ibimọ yi yio jẹ idi kan fun “ayọ nlanla? niha ọdọ “gbogbo enia.” Abajọ ti irohin angeli na nipa ibimọ na fi jẹ irohin yere, ki iṣe fun ọrun nikan, ṣugbọn pẹlu fun awọn enia lori ilẹ aiye!29. Bawo li awọn oluṣọ-agutan ṣe di ẹlẹri ti o fojuri bibi Messiah na?
29 Angeli na ti fifun awọn oluṣọ agutan “ami” ifihan na, nitorina nisisiyi nwọn le di ẹlẹri ti o fojuri ibimọ Messiah na.
“O si ṣe, nigbati awọn angeli na pada kuro lọdọ wọn lọ gi ọrun, awọn ọkunrin oluṣọ-agutan na ba ara wọn gọ pe, i jẹ ki a lọ tárà si Betlehemu, ki a le ri ohun ti o ṣẹ̀, ti [Jehofah] fihan fun wa. Nwọn si wá lọgan, nwọn si rì Maria, ati Josefu, ati ọmọ-ọwọ na, o dubulẹ ninu ibujẹ ẹran. Nigbati nwọn si ti ri i, nwọn sọ ohun ti a ti wi fun wọn nipa ti ọmọ yi. Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o gbọ si nkan wọnyi, ti a ti wi fun wọn lati ọdọ awọn oluṣọ-agutan wa. Ṣugbọn Maria pa gbogbo nkan wọnyi mọ, o nrò wọn ninu ọkàn rẹ̀. Awọn oluṣọ-agutan si pada lọ, nwọn nfi ogo fun Ọlọrun, nwọn si nyìn i, nitori ohun gbogbo ti nwọn ti gbọ ati ti nwọn ti ri, bi a ti wi i fun wọn.”—Luku 2:15-20.
30. Nipa kikẹ̀ “”ihinrere ayọ nla” yi silẹ, bawo ni awa yio ṣe ṣe ipalara fun ara wa?
30 Nipa bayi ibimọ wundia lọna iyanu yi ki iṣe itan àlẹ kankan. Awọn angeli ọrun ti jẹri si i, awọn ẹlẹri ti o si ṣe oju rẹ̀ ti jẹri si i. Luku oniṣegun na ti ṣe iwadi funrarẹ̀ o si ti ṣe akojọ irohin pataki yi fun wa. (Luku 1:1-4; Kolosse 4:14) A wulẹ npa ara wa lara bi a ko ba tẹwọgba ẹri ti o daniloju yi. Awa wulẹ nsọ ara wa di alailayọ nipa fifi pẹlu ọkàn igberaga kọ “ihinrere ayọ nla” yi silẹ.
31. Nigbawo ni Josefu mu Jesu gẹgẹ bi agbaṣọmọ rẹ̀ ti o si ṣe iwẹnumọ pẹlu iya ọmọ na?
31 Li ọjọ kẹjọ bibi rẹ̀ a kọ ọmọ na ni ila ninu ara, gẹgẹ bi ti awọn ọmọkunrin Ju miran ti a bí labẹ Ofin Luku 2:21; Galatia 4:4, 5) Li akoko na, Josefu fihan gbígbà ti on gbà Jesu ṣe ọmọ gẹgẹ bi agbaṣọmọ rẹ̀. On ko gba ọmọ àlẹ̀ ṣọmọ, ṣugbọn o dádòbò Jesu lodi si ẹsun eke ti jijẹ ọmọ agbere kan. Ni ogoji ọjọ ti a bi Jesu, Josefu mu ki Maria gbe akọbi ọmọkunrin rẹ̀ wá si Jerusalemu lati fi i han ninu tempili fun Jehofah ati lati ṣe ẹbọ iwẹnumọ fun iya rẹ̀ ati fun baba ti o gba ọmọkunrin na ṣọmọ. (Luku 2:22-24: Lefitiku 12:1-8) Ọba Herodu ko mọ gbogbo eyi.
Mose. (32. (a) Maria ha bi awọn ọmọkunrin ati ọmọbirin miran bi? (b) Jesu ti a gba ṣọmọ nisisiyi ni awọn ẹtọ wo lori ijọba Dafidi ti a mu kuro fun sá kan?
32 Nigbati o ṣe Maria tun dapọ pẹlu ọkọ rẹ̀ Josefu o si bi awọn ọmọ fun u. Ajkọsilẹ na fihan pe o kere tan fun ọdun mejila lẹhin bibi Jesu Josefu mba a lọ lati gbepọ pẹlu Maria. Eyiyi fi aye silẹ fun u lati ni awọn ọmọ lati ọdọ rẹ̀. Akọsilẹ na sọrọ nipa awọn ọmọ mẹrin, Jakobu, Josefu, Simoni ati Juda, ati awọn ọmọbirin miran pẹlu lati ọdọ Maria. Awọn wọnyi di arakunrin ọmọ iya ati arabirin ọmọ iya fun Jesu akọbi rẹ̀. (Luku 2:41-52; Matteu 13:53-56; Marku 6:1-3; Iṣe 1:14) Ṣugbọn, nitoripe Josefu gba akọbi ọmọkunrin rẹ̀ ṣọmọ gẹgẹ bi tirẹ̀ funrarẹ̀, Josefu ta atare rẹ̀ fun Jesu ẹtọ labẹ ofin ti on ní lori ijọba Dafidi babanla rẹ̀. Pẹlupẹlu, nipa jijẹ akọbi Maria nipa ti ara nipasẹ iṣẹ iyanu Ọlọrun, Jesu jogun ẹtọ abinibi si ijọba Dafidi ti a mu kuro fun igba diẹ nigbana. Ni pipese itan idile baba nla rẹ̀ Josefu, opitan na Matteu pe e ni Messiah, wipe: “Iwe iran Jesu Kristi, [Heberu: Messiah] ọmọ Dafidi ọmọ Abrahamu.”—Matteu 1:1. Tun wo Luku 3:23-38, ti o fi itan iran Maria han.
33, 34. Eṣe ti Ọba Herodu ko fi ṣe aṣeyọri lati pa Messiah ma, esitiṣe ti a fi npe Jesu ni “ara Nasareti”?
33 Bibi Jesu laipẹ pupọ ṣáju iku Ọba Herodu Nla ki iṣe ihinrere fun alakoso Jerusalemu ara Edomu na. O pe afiyesi ara rẹ̀ si ibimọ na, ki iṣe nipasẹ angeli Jehofah tabi nipasẹ awọn oluṣọ-agutan Betlehemu, ṣugbọn nipasẹ awọn aworawọ lati ila orùn, awọn ọkunrin ti o wà labẹ agbara ẹmi eṣu eyiti a dẹbi fun ninu Ofin Mose.—Deuteronomi 18:9-14; Isaiah 47:12-14; Danieli 2:27; 4:7; 5:17.
34 Ni afin Herodu a nilati kọkọ tọkasi asọtẹlẹ Mika 5:2 fun awọn aworawọ na ki ohun ti ntan yanranyanran ti nwọn rò pe o jẹ “irawọ” to ṣe amọna wọn de Betlehemu ati si ibiti a gbe Jesu wò si. Ọlọrun fun wọn ni ikilọ atọrunwa ninu àlá kan ki nwọn maṣe tun pada lọ sọ fun Herọdu apania na. Ki a maṣe dà ipetepero rẹ̀ lati pa Messiah rú, Herodu mu ki a pa awọn ọmọkunrin lati ọlọdun meji wá si isalẹ ni Betlehemu, ṣugbọn a ko ri Jesu pa. Nipasẹ ikilọ angeli, Josefu ati Maria ti gbe e lọ si Egipti. Herodu ku, ti o fi ọmọ rẹ̀ Arkelau silẹ gẹgẹ bi ọba Judea, pẹlu Betlehemu. Nitorina, a ko gbe Jesu pada wá si Betlehemu mọ ṣugbọn a gbe e lọ si ariwa si Nasareti ni Galili, nibiti a ti tọ́ ọ dagba. Idi ni yi ti a fi npe e ni Jesu ara Nasareti, ki iṣe Jesu ara Betlehemu.—Matteu 2:1-23; 21:11.
AṢIWAJU KAN FI MESSIAH NA HAN
35. Tani yio fi Messiah na hanni, ki si ni ohun ti ẹni yi nwasu rẹ̀?
35 Messiah na li ao fihan fun orilẹ-ede Israeli nipasẹ aṣiwaju kan, gẹgẹ bi asọtẹlẹ Malaki 3:1 ti wi. (Leeser; JPS) Eyi fihan pe o jẹ ọmọkunrin na ẹniti angeli Gabrieli sọ pe ao fifun Sekariah alufa arugbo na ati Elisabeti aya rẹ̀ arugbo na ati ẹniti Sekariah yio pe ni Johannu. (Luku 1:5-25, 57-80) Ni ibẹrẹ iruwe ọdun 29 C.E., nigba iṣakoso ọdun kẹdogun ti Teberiu Kesari, “ọrọ Ọlọrun tò Johannu ọmọ Sekariah wá ni iju. O si wá si gbogbo ilẹ iha Jordani, o nwásu baptism ironupiwada fun imukuro ẹṣẹ.” (Luku 3:1-3) O nwásu fun awọn wọnni ti o jade wa lati fetisi i, wipe: “Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ̀.” (Matteu 3:1; 2) Oniwasu yi di ẹniti a npe ni “ohannu, ẹniti o mbaptisi.”—Marku 1:1-4.
36. Nigbawo. ati éṣe ti Jesu fi lọ sọdọ Johannu lati baptisi, ẹri atọrunwa wo li a si fifunni fun itẹwọgba eyi?
36 Lẹhin riri Johannu ti o kún fun iṣẹ ni wiwasu ati ṣiṣe baptism fun nkan bi oṣu mẹfa, Jesu mu nkan ṣe. O mò pe on nilati di aṣoju lori ilẹ aiye fun “ijọba ọrun.” Nigba ikore ọdun na, 29 C.E., Jesu di ẹni ọgbọn ọdun. O fi iṣẹ gbẹna-gbẹna silẹ nibẹ ni Nasareti o si fi iya rẹ̀ silẹ nibẹ pẹlu awọn ọmọkunrin ati ọmọbirin rẹ̀ miran o si lọ lati wá Johannu ri, onṣẹ ti a ran ṣaju rẹ̀. Orin Dafidi 40:6-8. (Heberu 10:1-10) Nitorina o lọ, ki iṣe lati baptisi ni apẹrẹ ironupiwada fun awọn ẹṣẹ, bikoṣe lati baptisi ni apẹrẹ fifi ara rẹ̀ han lati ṣe ifẹ Ọlọrun fun u fun ọjọ iwaju. Bawo ni Ọlọrun ṣe fi itẹwọgba rẹ̀ han? A ka pe:
O ni awọn ọrọ asọtẹlẹ ti Ọba Dafidi sọ lọkan gẹgẹ bi a ti kọ ọ sinu“Nigbana ni Jesu ti Galili wá si Jordani gọdọ Johannu lati baptisi lọdọ rẹ̀. Mugbọn Johannu kò fun u, wipe, Emi li à bá baptisi lọdọ rẹ, iwọ si tò mi wá? Jesu si dahun, o wi fun u pe, Jọwọ rẹ̀ bẹ na: nitori bẹli o yẹ fun wa lati mu gbogbo ododo gẹ. Bẹli o jọwọ rẹ̀. Nigbati a si baptisi Jesu tan, o jade lẹsẹkanna lati inu omi, wa; si wò o, ọrun sí silẹ fun u, o si ri ẹmi Ọlọrun sọkalẹ bi adaba, o si bà le e: Si kiyesi i, ohùn kan lati ọrun wá, nwipe, Eyi ni ayanfẹ ọmọ nmi, ẹniti inu mi dun si gidigidi.”—Matteu 8:13-17.
37. Kini Johannu jẹri si fun awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ nipa ẹniti Jesu jẹ, esitiṣe ti o fi tọka si i gẹgẹ bi ẹniti ao fi ṣe irubọ?
37 Johannu Oniribọmi ri ohun ti o ṣẹlẹ o si gbọ ohun Baba ti mbẹ li ọrun. Lẹhinna o jẹri fun awọn ọmọẹhin rẹ̀ ohun ti on ti ri ti on si ti gbọ ti Ọlọrun sọ lati ọrun, o si jẹri, wipe: “Emi si ti ri, emi si ti njẹri pe, Eyi li Ọmọ Ọlọrun.” Johannu si tun tọka si Jesu ti a baptisi na gẹgẹ bi ẹniti ao fi rubọ fun igbala araiye, wipe: “Wo o, Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹniti o kô ẹṣẹ aiye lọ!” (Johannu 1:29-34) Ẹri Johannu Oniribọmi na ko ha yẹ fun itẹwọgba ati igbagbọ wa loni bi? Bẹni, nitotọ!
38. (a) Isọkalẹ ẹmi Ọlọrun sori Jesu tumọsi kini fun u? (b) Iye “ọsẹ ọdun” wo li o dopin nibẹ, kini si gbọdọ ṣẹlẹ nigba ọsẹ ti o tẹle e?
38 Isọkalẹ ẹmi mimọ Ọlọrun sori Jesu ti a ti baptisi tumọsi ju jijẹ Ọmọ Ọlọrun ti ẹmi lati igba yi lọ pẹlu imupadabọ sipo rẹ̀ si iye ti ẹmi li ọrun li ọjọ iwaju. O si tun tumọsi fifi ami ororo Ọlọrun yàn a. Nisisiyi niti totọ on di Ẹni Ororo na, Messiah na, tabi, ni ede Griki, Kristi. Nihin ni imuṣẹ asọtẹlẹ ni rẹgirẹgi. Nihin, ni ọdun 29 C.E., awọn (ọdun-) ọsẹ meje ati awọn (ọdun-) ọsẹ mejilelọgọta (apapọ ọdun 483) dopin pẹlu imujade fini Ororo na, Messiah na, Kristi na. (Danieli 9:25) Nisisiyi adọrin ọsẹ (ọdun-) nilati bẹrẹ, ni idaji eyiti Messiah na yio “mu ki a dẹkun ẹbọ, ati ọrẹ-ẹbọ” nipa pipese ara on funrarẹ̀ gẹgẹ bi ẹbọ enia kan, ki a si “ké” e kuro ninu iku irubọ gẹgẹ bi Ọdọ-agutan Ọlọrun.—Danieli 9:26, 27.
39. Nibo ati nigba iṣẹlẹ wo ni Jesu Kristi pe afiyesi si imuṣẹ asọtẹlẹ Isaiah. 61:1-3 ninu rẹ̀?
39 Bẹ gẹgẹ, pẹlu, asọtẹlẹ Isaiah 61:1-3 li a muṣẹ nipa ifororoyan Messiah na pẹlu ẹmi Jehofah. Ororo lasan li a fi yan Dafidi, ṣugbọn nihin a fi ẹmi mimọ yan Ọmọ ati Oluwa Dafidi. Ni ọdun ti o tẹle e, nigbati Jesu pada si Nasareti, ki iṣe lati ṣe iṣẹ gbẹnagbẹna, bikoṣe lati wasu ninu sinagogu, o pe afiyesi si imuṣẹ asọtẹlẹ Isaiah ninu rẹ̀. Akọsilẹ na ninu Luku 4:16-21 sọ fun wa:
“A si fi iwe woli Isaiah fun u. Nigbati o si gí iwe na, o ri ibiti a gbe kọ ọ pe, ẹmi [Jehofah] mbẹ lara mi, Nitoriti o fi ami ororo yan mi lati wásu ihinrere fun awọn otogi; o ti rán mi wa lati ṣe iwosan awọn ọkàn onirobinujẹ, lati wasu idasilẹ fun awọn igbekun, itunriran fun awọn afọju, ati lati jọwọ awọn ti a pa lara lọwọ, lati kede ọdun itẹwọgba [Jehofah]. O si pa iwe na de, o tun fi i fun irangẹ, o si joko. Gbogbo awọn ti o mbẹ ninu sinagogu si tẹjumọ ọ. O si bẹrẹ si iwi fun wọn pe, Loni ni iwe-mimọ yi gẹ li eti nyin.”
40, 41. (a) Eṣe ti Satani fi fẹ ba iṣotitọ Jesu ẹni ami ororo na jẹ ni pataki? (b) Kini iyọrisi didanwo ti Oludanwo na dan Jesu wò?
40 Ejo Nla na, Satani Eṣu, mò pe Jesu ẹni ami ororo yi ni “iru-ọmọ” Messiah “obirin” Ọlọrun li ọrun. Nihin, nisisiyi, ninu gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun” ni pataki eyi jẹ òkan ẹniti Ejo Nla na yio fẹ lati ba iṣotitọ rẹ̀ jẹ, si ẹgan titobijulọ fun Ọlọrun. Nitorina o sunmọ Jesu ninu aginju Judea, nibiti Jesu lọ lojukanna lẹhin baptismu rẹ̀ ti a si ti fi ẹmi Jehofah yan a, lati lo ogoji ọjọ nibẹ. Ejo Nla na gbiyanju lati dán Jesu wò: Lati fihan nipa aṣefihan fun Eṣu pe on jẹ ọmọ Ọlọrun o nilati yi awọn okuta pada lọna iyanu si akara tabi o nilati mu ki awọn angeli alaiṣe-fojuri na gbe e li ọwọ wọn lẹhinti o ba ti bẹ silẹ funrarẹ̀ lati ori ṣonṣo tempili ni Jerusalemu.
41 Lakotan, ninu isapa igbekuta kẹta ati eyiti o kẹhin, Oludanwo na fi “gbogbo ilẹ ọba aiye ati gbogbo ogo wọn” han Jesu li ẹ̀rẹ̀ fun kiki iṣẹ ijọsin kan lati Matteu 4:1-10.
ọdọ Jesu. Fun igba kẹta Jesu fa ọrọ yọ lati inu Ọrọ Ọlọrun o si wip: “[Jehofah] Ọlọrun rẹ ni ki iwọ ki o foribalẹ fun, on nikanṣoṣo ni ki iwọ má sìn.”—42. Bawo ni iriri Jesu nihin ṣe ṣe dédé pẹlu lilo ti Mose lò ogoji ọjọ lori Oke Horebu pẹlu angeli Ọlọrun?
42 Awọn angeli nwò didán ti a ndán iṣotitọ Messiah yi wò ninu iṣotitọ rẹ̀ si Ọlọrun Ọga Ogo Julọ. Nitorina nisisiyi, nigbati Eṣu pada lọ ninu itiju, “si kiyesi i, awọn angeli tọ̀ ọ wa, nwọn si nṣe iranṣẹ fun u.” (Matteu 4:11; Marku 1:13) Tipẹtipẹ ṣaju ni Mose ti wà li ogoji ọjọ pẹlu angeli Jehofah lori Oke Horebu ni aginju Sinai; nisisiyi Jesu Messiah, lẹhin ogoji ọjọ áwẹ̀ ati ṣiṣe aṣaro ni aginju Judea, muratan lati wọ inu iṣẹ rẹ̀ fun gbogbo enia pẹlu igbẹkẹle ni ilẹ Israeli. Eksodu 24:18.
[Alaye Isale Iwe]
^ ìpínrọ̀ 20 Wo Juda, ẹgẹ 9; Ifihan 12:7. Fun ijiroro iṣaju ati kikun nipa eyi, wo iwe E. W. Hengstenberg, ti a npe ni “Christology of the Old T’estament and Commentary,” Iwe 4, oju iwe 301-304 (ti a tẹjade ni 1836-1839 C.E.).
[Ibeere]
1. Nigbawo ni atunbi ilẹ kan ati orilẹ-ede kan ṣẹlẹ?
28. Tani ogo yẹ fun li akoko na, awọn wo li alafia si wa fun, ati “ihinrere ayọ nla” pẹlu?