Nigbati Enia Wà pẹlu Ọlọrun Ni Paradise
Ori 3
Nigbati Enia Wà pẹlu Ọlọrun Ni Paradise
1. Bawo li o ti pẹ to ti Ọlọrun fi jẹ Ẹni kan ṣoṣo na ti o wà, esitiṣe?
AWA ha ti ronu nigbakan ri nipa ohun ti o wà ninu gbolohun ọrọ na “Ẹlẹda ọrun,” ati “Ọlọrun, ẹniti o dá ohun gbogbo”? Awọn ọrọ wọnni tumọ si pe igba kan wà nigbati Ọlọrun nikan wà. (Isaiah 42:5: Efesu 3:9) Ko si ẹda kan kan ti o wà. Nitorina fun igba pipẹ sẹhin Ọlọrun yi nikan wà fun ara rẹ̀ on ko si ti di Ẹlẹda kan. Idi ni yi ti woli Mose fi wi ninu adura si Ọlọrun pe: “Ki a to bi awọn oke nla, ati ki iwọ ki o to da ilẹ on aiye, ani lati aiye-raiye, iwọ li Ọlọrun.” (Orin Dafidi 90:2, itumọ ti Byington) Ninu gbogbo akoko pipẹ sẹhin na ṣaju iṣẹda o ṣeṣe fun Ọlọrun lati gbadun Ara Rẹ̀.
2. Nigbati o ṣe Ọlọrun pete lati da kini, nipa bayi ti o si mu ẹrù iṣẹ wo wá fun ara rẹ̀?
2 Akoko na de nigbati Ọlọrun pete lati di Baba kan. Eyi ko tumọ si lati jẹ Ẹlẹda awọn ohun alailẹmi, awọn nkan alailoye. O tumọ si lati fi iwaláyé fun awọn ẹda oloye, fun awọn ọmọ pẹlu ifarajọ ọ diẹ gẹgẹ bi Baba wọn. Nipa bayi o pete lati tẹwọgba a fun ra Rẹ̀ ẹru iṣẹ gbigbe idile ọlọmọ dide. Iru awọn ọmọ wo li On pete lati mu jade li akọkọ? Ki iṣe awọn ọmọ enia, nitoripe ninu ọran bẹ on ti nilati pese ilẹ aiye kan li akọkọ lori eyiti nwọn le gbe. Lọna ti o lọgbọn ninu, Ọlọrun yio pese awọn ọmọ, gẹgẹ bi On, ti o jẹ ti ọrun, ti o jẹ ti ẹmi gẹgẹ bi On ti jẹ ti ẹmi. Nipa bayi nwọn yio jẹ ọmọ ẹmi, ti o le ri i ti nwọn si le de iwaju rẹ̀ ni táràtà ati awọn ẹniti on le ba sọrọ ni táràtà.
3. Ani ṣaju iṣẹda ilẹ aiye wa, bawo li a ti ṣe pe afiyesi wa si wiwà awọn ọmọ Ọlọrun li ọrun?
Jobu 1:6) Ipade keji ti awọn ọmọ Ọlọrun otitọ wọnni li ọrun li a pe afiyesi wa si ninu Jobu 2:1. Otitọ na pe awọn ọmọ ẹmi Ọlọrun wọnyi waláyé ninu awọn ọrun ti a ko le fojuri ṣaju iṣẹda aiye wa li a tẹnumọ nigbati Ọlọrun ba ọkunrin na Jobu sọrọ lati inu airi wá ti o si bi i lere: “Nibo ni iwọ wà nigbati mo fi ipilẹ aiye sọlẹ? . . . Nigbati awọn irawọ owurọ jumọ kọrin pọ, ti gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun nho iho ayọ?” Dajudaju awọn ọmọ Ọlọrun wọnni, ti nwọn ndán yanranyanran bi irawọ owurọ ninu awọn ọrun, ní ifẹ si ete Ọlọrun ni dida ilẹ aiye wa nwọn si gbadun ọna ti on gba da ilẹ aiye, “ti o nà iha ariwa ọrun ni ibi ofurufu, o si fi aiye rọ̀ li oju ofo.”—Jobu 38:4-7; 26:7.
3 Iwaláyé iru awọn ọmọ Ọlọrun ti ẹmi bẹ ki wulẹ ṣe imefo ti isin. Ẹniti o kọ iwe Jobu ninu Bibeli, o ṣéṣe ki o jẹ woli Mose, sọrọ nipa awọn wọnyi ninu ori ti o bẹrẹ iwe na, wipe: “Njẹ, o di ọjọ kan, nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wá ípé niwaju [Jehofah].” (4. (a) Kini a le fi pẹlu ẹtọ pe ọmọ ekini ti Ọlọrun kọkọ dá niti iṣẹda ati idile Ọlọrun? (b) Bawo li “ọgbọn” ṣe sọrọ ara rẹ̀ ninu Owe 8:22-31?
4 Tani ekini ninu ọmọ Ọlọrun ti ẹmi ti On dá? Ẹni yi, nitori ilọlaju rẹ̀, li ao fi pẹlu ẹtọ pè ni ibẹrẹ iṣẹda Ọlọrun. Nitori Ẹni yi jẹ memba ekini ninu idile Ọlọrun li ọrun, a si tun le pe e ni akọbi gbogbo ẹda. Ironu wa nipa eyi nihinyi rán wa leti ohun ti a sọ ninu ori kẹjọ iwe Owe, nibiti a ti ṣapejuwe ọgbọn atọrunwa gẹgẹ bi ẹnikan ti o nsọrọ nipa ara rẹ̀. Ṣugbọn o, ninu itumọ Owe li ede Heberu li akọkọ, ọrọ na “ọgbọn”? (hhakh-mah’) wa li ede ti abo o si sọrọ nipa rẹ̀ gẹgẹ bi abo enia kan. (Owe 8:1-4) Biotiwukiori, ọgbọn atọrunwa ko ní iwalayè laye ọtọ kuro lọdọ Ọlọrun. Igba gbogbo li ọgbọn ma nwà ninu Rẹ̀ nitorina a ko dá a. Nitori idi eyi o dun-mọni lati gbọ bi ọgbọn ti nsọrọ ara rẹ̀ gẹgẹ bi abo enia kan, nigbati o wi ni pataki bayi pe:
“Oluwa [Heberu: JHVH] pese mi ni ipilẹṣẹ iwa rẹ̀, gaju iṣẹ rẹ̀ atijọ. A ti yan mi lati aiyeraiye, lati ipilẹṣẹ, tabi ki aiye ki o to wà. Nigbati ọgbun ko si, a ti bi mi; nigbati ko si orisun ti o kun fun omi pipọ. Ki a to fi idi awọn oke-nla sọlẹ, ṣaju awọn oke li a ti bi mi, Nigbati ko ti ida aiye, tabi pẹtẹlẹ, tabi ori erupẹ aiye. Nigbati o nṣe ipilẹ awọn ọrun, emi wà nibẹ: nigbati o fi oṣuwọn ayika le oju ọgbun. Nigbati o sọ awọsanma lọ́jọ soke: nigbati o fi agbara fun orisun ibú: nigbati o fi aṣẹ rẹ̀ fun okun, ki omi rẹ̀ ki o maṣe kọja ẹnu rẹ̀: ati ofin rẹ̀ fun ipilẹ aiye. Nigbana, emi wà lọdọ rẹ̀, bi oniṣẹ: emi si jẹ didun-inu rẹ̀ lojojumọ, emi nyọ̀ nigba gbogbo niwaju rẹ̀; emi nyọ ni ibi-itẹdo aiye rẹ̀: didun-inu mi si wà sipa awọn ọmọ enia.”—Owe 8:22-31, Rabbi Isaac Leeser’s translation, ti 1858.
5. Eṣe ti awọn aṣáju Ju ṣe nṣaniyan nipa bi a ṣe lo awọn ọrọ inu iwe Owe wọnni ni Sanmani Igba Tiwa?
5 Aniyan awọn aṣaju Ju ni nipa itumọ ti a le fifun awọn ẹsẹ Bibeli ti mbẹ loke yi. Ninu iwe Owe ti Soncino Press tẹjade ni 1945, a kà ninu alaye isalẹ apa yi pe: “Fun onkawe Ju itumọ yi ṣe pataki ju loju lilo ti awọn Father Ṣoṣi akọkọ-bẹrẹ gba lo apa yi fun ẹkọ Kristi.” * Biotiwukiori, Owe 8:22 sọrọ nipa ohun kan gẹgẹ bi ohun ti a dá gẹgẹ bi ibẹrẹ ọna Jehofah Ọlọrun, gẹgẹ bi “ipilẹṣẹ iwà rẹ̀, ṣaju iṣẹ rẹ̀ atijọ.” Ọgbọn “ti a dá!”
AWỌN KERUBU, ANGELI, SERAFU
6. Kini a wi nipa awọn kerubu ninu Genesisi ati Orin Dafidi?
6 Iwe Mimọ pin “awọn ọmọ Ọlọrun” wọnyi li ọrun si, o kere tan, ipa mẹta. Ekini ninu awọn ẹgbẹ wọnyi lati mẹnukan ni ti “awọn kerubu.” Genesisi 3:24 ṣapejuwe iye awọn kerubu ti Ọlọrun mu duro ni ila-orùn Paradise ilẹ aiye lati “má ṣọ́ ọna igi iye na.” Nipa sisunmọ ti awọn kerubu sunmọ ijoko ọla aṣẹ ti Ọlọrun wa lori rẹ̀ ati itilẹhin olótọ ti nwọn fun u, Asafu onipsalmu na sọrọ, wipe: “Iwọ ti o joko lárin awọn kerubu, tàn imọlẹ jade.” (Orin Dafidi 80:1 ati alaye akọle) Orin Dafidi 99:1 pe afiyesi si ohun kanna, wipe: “[Jehofah] jọba; jẹ ki awọn enia ki o wariri: o joko lori awọn kerubu; ki aiye ki o ta gbọngbọn.”
7. Nigbawo ati bawo ni Ọba Hesekiah ṣe so awọn kerubu pọ mọ Ọlọrun?
7 Pẹlupẹlu, Ọba Hesekiah, ẹniti o nsọju fun Ọlọrun Ọga Ogo lori itẹ ti a le fojuri ni Jerusalemu, so awọn kerubu pọ mọ itẹ Ọba Alaṣẹ Agbaiye li ọrun, nigbati o gbadura pe: “[Jehofah] awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, ti ngbe árin awọn kerubu, iwọ li Ọlọrun, ani iwọ nikan ninu gbogbo ijọba aiye: iwọ li o dá ọrun on aiye.” (Isaiah 37:16) Nipa bayi, leralera, Ẹlẹda nla na, Alaṣẹ Agbaiye, li a fihan pe o joko lori itẹ lori awọn “ọmọ Ọlọrun” ti a mọ gẹgẹ bi kerubu.
8. Kini ninu igbesi aiye Abrahamu, Lọti ati Jakobu li o tì i lẹhin pe awọn angeli wà?
8 Ni afikun si awọn kerubu “ọmọ Ọlọrun!” bẹ, li ẹgbẹ awọn angeli li apapọ. Ko si idi kankan ninu itan lati ṣiyemeji wiwà awọn ẹda ẹmi ti a ko le fojuri wọnyi, nitoripe nwọn ti ṣe ifarahan ọpọlọpọ ti o daniloju fun awọn enia. Ni nkan bi ọdun 1919 B.C.E. awọn angeli mẹta ti nwọn jẹ aṣoju Jehofah Ọlọrun gbe àwọ̀ enia wọ nwọn si farahan Abrahamu babanla na bi o ti joko labẹ awọn igi kan ni Mamre ni ilẹ Kenaani ni Palestine. Kete lẹhinna, meji ninu awọn angeli ti o di enia wọnyi ṣe ibẹwo sọdọ Lọtu ọmọ ẹgbọn Abrahamu ni ilu Sodomu lẹba Okun Oku, ọjọ kan ṣaju ki a to pa ilu buburu yi run pẹlu ina ati sulfuru ti a rọjo rẹ̀ lati inu afẹfẹ wa sori ilu na. (Genesisi 18:1 titi de 19:29) O ju ọgọrun ọdun kan lẹhinna, Jakobu ọmọ-ọmọ Abrahamu npadabọ wa si iha gusu nibiti babanla rẹ̀ ti saba má npagọ si, o si ni iriri ohun ti o ṣẹlẹ ninu Genesisi 32:1, 2: “Jakobu si nlọ li ọna rẹ̀, awọn angeli Ọlọrun si pade rẹ̀. Nigbati Jakobu si ri wọn, o ni, Ogun Ọlọrun li eyi: o si sọ orukọ ibẹ na ni Mahanaimu [ti o tumọ si ‘Agọ Meji’].”
9. (a) Kini ọrọ na “angeli” tumọsi pẹlu? (b) Bawo li a ṣe nlo awọn angeli, rekọja agbara awọn enia lati ṣe idìwọ fun wọn?
Malaki 3:1, nibiti a ti ka pe: “Kiyesi i, emi o ran onṣẹ (tabi, angelil mi, yio si tún ọna rẹ ṣe niwaju mi.” Ni ọpọlọpọ igba li a ti ran awọn angeli ọrun ni iṣẹ lati jiṣẹ tabi lati ṣe iṣẹ Pataki kan. Enia ko le dí wọn lọwọ ninu ṣiṣe iṣẹ ti Ọlọrun yàn fun wọn nitoripe a fun wọn li agbara ati ipa ti o ju agbara ati ipa enia. Onipsalmu na mọ otitọ yi, o si wipe: “[Jehofah] ti pese itẹ rẹ̀ ninu ọrun; ijọba rẹ̀ li o si bori ohun gbogbo. Ẹ fi ibukun fun [Jehofah], ẹnyin angeli rẹ̀, ti o pọ ni ipa, ti nṣe ofin rẹ̀, ti nfi eti si ohun ọrọ rẹ̀. Ẹ fi ibukun fun [Jehofah], ẹnyin ọmọ ogun rẹ̀ gbogbo; ẹnyin iranṣẹ rẹ̀, ti nṣe ifẹ rẹ̀.”—Orin Dafidi 103:19-21.
9 Ọrọ Bibeli pẹlu fun angeli tumọ si “onṣẹ” tabi “iranṣẹ,” gẹgẹ bi o ti wà ninu10. (a) Kini iṣarasihuwa awọn serafu si Ọlọrun? (b) Iriri wo ni Isaiah ni pẹlu awọn serafu, eyi si fi kini han?
10 Sibẹ ẹgbẹ miran ninu “awọn ọmọ Ọlọrun” li ọrun ni awọn serafu. Awọn ẹda ẹmi wọnyi kún fun ọwọ gan niwaju Ọlọrun. Eyiyi li a fihan ninu iran agbayanu ti a fifun woli Isaiah. Ẹ: jẹki a kiyesi apejuwe rẹ̀: “Li ọdun ti Ussiah ọba ku [778/777 B.C.E.], emi ri [Jehofah] joko lori itẹ ti o ga, ti o si gbe ara soke, iṣẹti aṣọ igunwa rẹ̀ kún tempili. Awọn serafu duro loke rẹ̀, ọkọkan wọn ni iyẹ mẹfa, o fi meji bo oju rẹ, o si fi meji bo ẹsẹ rẹ̀, o si fi meji fò. Ikini si ké si ekeji pe, Mimọ, mimọ, mimọ, ni [Jehofah] awọn ọmọ-ogun, gbogbo aiye kún fun ogo rẹ̀.” Woli Isaiah ri i pe o di ọranyan fun on lati kigbe jade ninu ibẹru iku nitori ipo aimọ rẹ̀. “Nigbana” Isaiah sọ fun wa, “ni ọkan ninu awọn serafu fò wá sọdọ mi, o ni ẹṣẹ-ina li ọwọ rẹ̀, ti o ti fi ẹ̀mú mú lati ori pẹpẹ wá. O si fi kàn mi li ẹnu, o si wipe, Kiyesi i, eyi ti kan ete rẹ, a mu aiṣedédé rẹ kuro, a si fọ ẹṣẹ rẹ nù.” (Isaiah 6:1-7) Ninu eyi a ri ifihan ifẹ ti awọn serafu ni fun riran wa lọwọ lati jẹ mimọ gẹgẹ bi Ọlọrun ti jẹ mimọ.
11. Bawo ni idile Ọlọrun ti “awọn ọmọ” li ọrun ti tobi to, esitiṣe ti ẹda wọn fi yatọ si ti awa enia?
11 Iye gbogbo awọn kerubu, serafu ati awọn angeli Danieli 7:9, 10) Iru iye ọpọlọpọ “awọn ọmọ Ọlọrun” mimọ bẹ fihan agbara iṣẹ iṣẹda nlanla ti Jehofah Ọlọrun Olodumare, Baba ti mbẹ li ọrun ní. On ní idile yiyanilẹnu ti awọn ọmọ onigbọran li ọrun. Awọn wọnyi ki iṣe awọn ẹda ẹlẹran ara ati ẹjẹ, nitoripe a ti dá wọn ṣaju ilẹ aiye wa lori eyiti awa ẹda ẹlẹran ara ati ẹjẹ ngbe. Nitorina awọn “ọmọ Ọlọrun” li ọrun wọnni jẹ ti ẹmi, gẹgẹ bi Ọlọrun ti jẹ, nwọn si yatọ patapata ninu ẹda si awa ẹda enia ti ngbe orilẹ-aiye.
”ọmọ Ọlọrun” wọnyi li ọrun jẹ ọpọlọpọ adọta ọkẹ. Woli Danieli ni Babiloni li a misi lati kọwe nipa iran na ti on ri nipa iran igbẹjọ kan li ọrun: “Mo si wò titi a fi sọ̀ ìtẹ wọnni kalẹ titi Ẹni-agba ọjọ na fi joko, . . . Ẹgbẹrun gbẹrun nṣe iranṣẹ fun u, ati awọn ẹgbẹgbarun nigba ẹgbárun [=100,000,000] duro niwaju rẹ̀: awọn onidajọ joko, a si ṣí iwe wọnni silẹ.” (12. Eṣe ti “awọn ọmọ Ọlọrun” li ọrun ko fi ní ninu rẹ̀ awọn ọkàn enia ti a ti ṣi nipo pada nisisiyi si ilẹ ọba ẹmi ti a ko le fojuri?
12 Nigbati o nfi iyatọ alailẹgbẹ ti o wà lárin Ọlọrun ati enia han (bi awọn ara Egipti igbánì) ati lárin ẹmi ati ẹran ara, asọtẹlẹ Isaiah 31:3 dá awọn ọmọ Israeli lẹkun kuro ninu yiyiju si ara Egipti ologun fun iranlọwọ, wipe: “Enia li awọn ara Egipti, nwọn ki iṣe Ọlọrun; ẹran li awọn ẹṣin wọn, nwọn ki iṣe ẹmi.” Pẹlupẹlu, ninu ọrọ ti o ṣe táràtà pe “awọn ọmọ Ọlọrun” li ọrun jẹ ti ẹda ti o yatọ patapata si enia, Orin Dafidi 104:1-4 wipe: “Fi ibukun fun [Jehofah] iwọ ọkàn mi. [Jehofah], Ọlọrun mi, iwọ tobi jọjọ: ọla ati ọlanla ni iwọ wọ̀ li aṣọ. Ẹniti o . . . ṣe ẹfúfù ni onṣẹ rẹ̀; ati ọwọina ni iranṣẹ rẹ̀.” Dajudaju Iwe Mimọ fagile ero isin na pe awọn angeli ọrun jẹ apakan awọn ọkàn enia ti o ti ṣipo-pada lati ilẹ aiye lọ si awọn ọrun ti a ko le fojuri. Gbogbo “awọn ọmọ Ọlọrun” ti ẹmi jẹ arakunrin, gbogbo wọn si jẹ awọn ọmọ Baba ọrun kanna.
IṢẸDA ENIA
13. Kini iṣarasihuwa baba totọ kan si idile kan ti on mu jade?
13 Baba totọ kan pese idile kan nitoripe on fẹran awọn ọmọ. On ko ni ifẹ lati mu awọn enia buburu tabi Owe 10:1; 28:24.
awọn eṣu jade ninu wọn tabi ki o ri itẹlọrun eyikeyi gba ninu fifi iya jẹ wọn tabi dida wọn loro. On ni ifẹ wọn ti o ga julọ li ọkan. On fẹ lati ri igbadun ninu wọn nitoripe nwọn fi aworan rẹ̀ han nwọn si jẹ iyi fun u nwọn si nfun u ni ẹ̀wọ ti o yẹ ati igbọran. Tipẹtipẹ, labẹ imisi atọrunwa, ọba kan ti on tikararẹ̀ jẹ baba ọpọlọpọ awọn ọmọ, wipe: “Ọlọgbọn ọmọ ṣe inudidun baba rẹ̀.” “Baba olododo ni yio yọ gidigidi: ẹniti o si bi ọmọ ọlọgbọn, yio ni ayọ ninu rẹ̀.”—14. Bawo li a ṣe fi Jehofah we baba enia kan ni biba awọn ọmọ lò?
14 Niti Baba ti mbẹ li ọrun na nipa iwa rẹ̀ si awọn ẹda rẹ̀ oloye, Dafidi onipsalmu na wipe: “Bi baba ti iṣe iyọ́nú si awọn ọmọ, bẹli [Jehofah] nṣe iyọ́nu si awọn ti o bẹru rẹ̀. Nitori ti o mọ ẹda wa; o ranti pe erupẹ ni wá.” (Orin Dafidi 103:13, 14) Ohun ti Jehofah nreti lati ọdọ awọn ọmọ rẹ̀, li on fihan, wipe: “Ọmọ a ma bọla fun baba, ati ọmọ-ọdọ fun oluwa rẹ̀: njẹ bi emi ba ṣe baba, ọlá mi ha dà? Bi emi ba si ṣe oluwa, ẹ̀rù mi ha dà?” (Malaki 1:6) Jehofah Baba ọrun na ko rẹlẹ si baba orilẹ aiye kan ni fifi awọn animọ ti o yẹ han si awọn ẹda Rẹ̀, nitoripe On wipe: “Emi o si dá wọn si gẹgẹ bi enia iti má dá ọmọ rẹ̀ si ti o nsìn i.”—Malaki 3:17.
15. Kini ete Ọlọrun ni didá awọn ọmọ ti ẹda rẹ̀ rẹlẹ ju ti awọn ọmọ ti mbẹ li ọrun, nipa bayi kini ao si fihan?
15 Pẹlu ohun ti ko dinku si ete onifẹ, Jehofah Ọlọrun pete lati di baba fun awọn ọmọ ti o jẹ ẹda titun kan. Eyiyi fihan pe nwọn ko ni jẹ ti ẹda ti ẹmi, ki iṣe ẹda ti ọrun. Tiwọn yio jẹ ti ẹda kan ti ko dán to ti ẹda ti ẹmi, nipa bayi nwọn yio wà labẹ álà kan ati ikalọwọko iru eyiti “awọn ọmọ Ọlọrun” li ọrun kò ní. Biọtiwukiori, eyi ko ni mu iṣoro kankan wá fun wọn, nwọn yio si ni igbadun ni pipe. Ẹda wọn yio jẹ ti ẹran ara ati ẹjẹ, tabi ẹda enia. Dida awọn ọmọ ti ẹda wọn rẹlẹ yi ki iṣe nitoripe Baba ọrun na ko ni itẹlọrun pẹlu idile titobi rẹ̀ ti awọn ọmọ ẹmi tabi pe o nfẹ nkan titun kan, afikun kan pẹlu eyiti on yio pese idaraya titun fun ara rẹ̀. Kakabẹ, o jẹ lati fihan siwaju si i ọgbọn titobi
Ọlọrun li oniríiru ọna gẹgẹ bi Ẹlẹda kan, ati pẹlu lati mu ifẹ rẹ̀ gborò si awọn ẹda miran sibẹ.16. (a) Fun dida idile ẹda enia, kini Ọlọrun gbọdọ kọkọ mu jade? (b) Kini ete rẹ̀ ti a kede fun didá ilẹ aiye wa?
16 Biotiwukiori, lakọkọ, On nilati pese ohun elo eyiti on yio lo lati dá idile yi ti o jẹ ti ẹda enia ati ibiti o ba a mu pẹlu fun idile enia yi lati waláyè ati lati gbe. Pẹlu eyi li ọkàn, On dá ilẹ aiye, planet kan ti o jẹ ti orùn ti o si jẹ apakan ninu idipọ titobi ti awọn irawọ ti a mọ nisisiyi gẹgẹ bi The Milky Way. Lori koko yi Bibeli Mimọ bẹrẹ itan rẹ̀ yiyanilẹnu, wipe: “Li atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun on aiye.” (Genesisi 1:1) Pẹlu abojuto onifẹ on mura awọn ipo ati ayika silẹ lori ilẹ aiye ti o tutu ti o si le pali fun awọn enia olugbe rẹ̀. Ete rẹ̀ fun ilẹ aiye yi li on sọrọ nipa rẹ̀, wipe:
“Bayi ni [Jehofah] wi, ẹniti o dá awọn ọrun; Ọlọrun tikararẹ̀ ti o mọ aiye, ti o si ṣe e; o ti fi idi rẹ̀ mulẹ, ko dá a lasan, o mọ ọ ki a le gbe inu rẹ̀.”—Isaiah 45:18.
17. Bawo ni Ẹlẹda na ṣe ri ohun ti idile enia rẹ̀ nfẹ tẹlẹ, bawo li on si ti pese awọn ohun ti a nfẹ na?
17 Idile enia rẹ̀ yio ni awọn ara ti o nilati ma mí ki o ba le gbe iwaláyè ro, nitorina o pese afẹfẹ yika aiye. Nwọn yio fẹ omi lati mu nitorina o pese pupọ eyini. Nwọn nfẹ onirúru igi ati ewebẹ fun onjẹ, eyi li On si pese fun wọn. Nwọn nfẹ imọlẹ òrùn fun ilera ati fun iriran, on si mu ekuru eyikeyi kuro ti o le ṣe idiwọ fun awọn itanṣan òrùn lati de ilẹ aiye, lẹhinna li o si ṣeto ikúku na ki itanṣan òrùn, imọlẹ oṣupa ati imọlẹ irawọ ba le de ori ilẹ aiye. Idile enia nfẹ awọn igba isimi ati orun dede, Oluṣeto nla fun ilẹ aiye na si mu ki o má yipo ki ọsan ba le má dé nigbati òru ba lọ. O mu ki awọn omi kún fun ẹja ati awọn ẹda omi miran, awọn ẹda abiyẹ lati má fò kakiri ninu afẹfẹ, ati awọn ọranko li oriṣiriṣi, ki gbogbo wọn si má sà ipa tiwọn ninu iṣeto igbesi aiye lori ilẹ aiye. Gbogbo eyi ni Ẹlẹda onifẹ ati ọlọgbọn na ṣe lárin ọjọ mẹfa akọkọ iṣẹda, eyiti on funrarẹ̀ pe ni awọn ọjọ.—Genesisi 1:1-25.
18. Nigbawo ati li “ọjọ” iṣẹda wo li Ọlọrun kede ete rẹ̀ lati fi opin si iṣẹda rẹ̀ lori ilẹ aiye?
Genesisi 1:26 pe: “Ọlọrun si wipe, Jẹ ki a dá enia li aworan wa, gẹgẹ bi ìrí wa: ki nwọn ki o si jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ẹranko, ati lori gbogbo ilẹ, ati lori ohun gbogbo ti nrako lori ilẹ.”
18 Nigbati igba akoko iṣẹda kẹfa npari lọ a ti mura awọn nkan silẹ ati nipa ilẹ aiye fun Baba ọrun na lati tẹsiwaju pẹlu bibẹrẹ idile enia. Nigbana li on kede ohun ti yio jẹ ogogoro iṣẹ iṣẹda rẹ̀ lori ilẹ aiye, bi a ti kà a ninu19. Bawo li awa ṣe le fihan boya Ọlọrun mba ara rẹ̀ sọrọ ninu Genesisi 1:26?
19 Ninu akọsilẹ iṣẹda yi li ede Heberu ọrọ na fun “Ọlọrun” ni e-lo-him’, eyiti o jẹ ọpọ ọrọ fun e-lo’ah, ọpọ ọrọ eyiti a lo nihin ninu Genesisi lati fi ọla ati ogo han, ki si iṣe ọpọ awọn ọlọrun, meji, mẹta tabi jubẹlọ. Idi ni yi ti awọn ọrọ iṣe ti o rinpọ pẹlu E-lo-him’ jẹ ẹyọkan ni iye. Nitorina nigbati a ba kà pe, “Ọlọrun [E-lo-him’] si wipe, Jẹ ki a,” ko tumọ si pe Ọlọrun mba ara rẹ̀ sọrọ. On ki iṣe mẹtalọkan, ọlọrun mẹta, ọlọrun kan ninu ẹni mẹta, ti ẹnikan ninu rẹ̀ yio fi wi fun ẹni meji ti o kù ninu rẹ̀ pe, “Jẹ ki a.” Ninu Genesisi 2:4 Ẹlẹda yi li a pe ni Jehofah Ọlọrun, lẹhinna, akọwe na, Mose wipe: “Gbọ, Israeli: [Jehofah] Ọlọrun wa, [Jehofah] kan ni.” Ko si Jehofah meji tabi mẹta, ẹyọ kan pere li o wà! Ọlọrun mẹta tabi mẹtalọkan ti a fi ẹnu lasan pe bẹ jẹ imujade ibọriṣa. O jẹ ọrọ odi eke.—Deuteronomi 6:4.
20. Pẹlu ilọgbọn-ninu julọ nwọn ọrọ na “Jẹ ki a dá enia” li a sọ si tani, esitiṣe ti o fi jẹ bẹ?
20 Nitorina, nigbati Ọlọrun (E-lo-him’) Wipe, “Jẹ ki a,” o kere tan on mba ẹlomiran kan sọrọ yatọ si on funrarẹ̀ ninu awọn ọrun ẹda ẹmi ti a ko le fojuri. Boya li o fi le jẹ pe Jehofah Ọlọrun yio má ba ọkan ninu awọn 100,000,000 angeli tabi jubẹlọ sọrọ nihin, awọn ẹniti nsin i ki o si ma bere ifọwọsowọpọ wọn ninu iṣẹda enia. O lọgbọn ninu julọ pe on yio má ba Ọmọ akọbi rẹ̀ li ọrun sọrọ, akọbi ninu gbogbo iṣẹda, ibẹrẹ
iṣẹda Ọlọrun. Ẹni yi, gẹgẹ bi akọbi ninu idile Ọlọrun li ọrun, yio jẹ ẹni na ti a nilati fun li ọla ati iyì ti jijẹ ẹniti a kesi lati ṣiṣẹ papọ pẹlu Baba rẹ̀ ọrun ninu iṣẹda enia lori ilẹ aiye. Eyiyi yio mu ki awọn ọran rọrun. Niwọnbi akọbi ọmọ li ọrun yi jẹ “aworan” Baba rẹ̀ ọrun ti o si jẹ “ìrí” rẹ̀ bẹ gẹgẹ, Ọlọrun le fi pẹlu ẹtọ. Wi fun u pe, “Jẹ ki a da enia li aworan wa, gẹgẹ bi ìrí wa.” Wiwà ti ẹnikan wà li aworan Ọlọrun ati gẹgẹ bi ìrí rẹ̀ ko le tumọ si lai pe ẹnikan dọgba pẹlu Jehofah Ọlọrun. “Aworan” ki iṣe ohun na gán!ỌKUNRIN EKINI NINU PARADISE
21. Nibo li o sọ pe a fi ọkunrin ti a ṣẹṣẹ dá na si ninu Paradise?
21 Genesisi, ori keji, ṣalaye iṣẹda enia ni kikun. Pẹlu apejuwe, Genesisi 2:7, 8 sọ fun wa: “[Jehofah] Ọlọrun si fi erupẹ ilẹ mọ enia: o si mí ẹmi iye si iho imu rẹ̀; enia si di aláyẹ̀ ọkàn. [Jehofah] Ọlọrun si gbin ọgba kan niha ila òrùn ni Edeni; nibẹ li o si fi ọkunrin na ti o ti mọ si.” Ninu itumọ Bibeli li ede Siria igbánì ọrọ na Paradise li a lo lati duro fun “ọgba”; itumọ Bibeli ti Douay pẹlu lo ọrọ na Paradise o si wipe: “Oluwa Ọlọrun si ti gbin paradise igbadun kan lati ibẹrẹ: nibiti on fi ọkunrin kan ti on ti mọ si.”—Genesisi 2:8, Dy.
22. Kini ironu isin ti o wọpọ ti awọn kan ngbiyanju lati fi sinu ohun ti Genesisi 2:7 sọ nitotọ?
22 Ẹ jẹki a tun ṣakiyesi lẹkansi i ohun ti Genesisi 2:7 wi nipa iṣẹda enia. On ha sọ wipe Jehofah Ọlọrun fi ọkàn kan ti o yatọ sinu ọkunrin na ti o si yatọ patapata si ara rẹ̀? Ohun ti ọpọlọpọ enia onisin fẹ tumọ ọrọ na si li eyini. Nitotọ, itumọ Bibeli Spanish, lati ọwọ F. Torres Amat—-S. L. Copello, ti 1942 C.E., nigbati a ba tumọ rẹ̀ si ede Yoruba, kà pe: “Nigbana ni Oluwa Ọlọrun fi erupẹ ilẹ mọ enia, o si mí si oju rẹ̀ emi tabi ẹmí iye, enia si di ẹniti o walayè pẹlu ọkàn onironu.” * Eyiyi yatọ gan si Douay Version ti Roman Catholic, ti o sọ wipe: “Enia si di aláye ọkàn.” Pẹlupẹlu, itumọ ti The Jewish Publication Society ti America tẹjade kà pe: “Enia si di aláye ọkàn.” Ki awọn onkawe wa ba le ri ohun ti ọrọ Heberu kọkan tumọsi ni gidi (lati ọtun si osi) a pese ni isalẹ yi aworan bi o ti ṣe ri gán apa yi ninu Genesisi 2:7 ninu The Interlinear Literal Translation of the Hebrew Old Testament, lati ọwọ G. R. Berry, ti a tẹjade ni 1896-1897:
OLUWA Ọlọrun na mọ enia lati inu erupẹ ilẹ, o si mí emí iye si iho imu rẹ̀; enia si di alayè ọkàn. 8 ¶ OLUWA Ọlọrun si gbin ọgba kan Edeni ninu ọgba kan Ọlọrun Jehofah gbin Ati 1 alayè 2 ọkàn kan (fun)
יְהוָֹה אֱלֹהִים אֶת־הָאָדָם עָפָר מִן־הָאֲדָמָה
,OLUWA Ọlọrun na mọ enia lati inu erupẹ ilẹ
וַיִּפַּח בְּאַפָּיו נִשְׁמַת חַיִּים וַיְהִי הָאָדָם
o si mí emí iye si iho imu rẹ̀; enia si di alayè ọkàn
8 לְנֶפֶשׁ חַיָּה וַיִּטַּע יְהוָֹה אֱלֹהִים גַּן בְּעֵדֶן
OLUWA Ọlọrun si gbin ọgba kan Edeni ninu ọgba kan Ọlọrun Jehofah gbin Ati ọkàn kan (fun)
23. Nigbati ara enia ba kú, kini nṣẹlẹ si ọkàn?
23 Niwọnbi Ọrọ Ọlọrun ti a misi ti wi kedere pe, “Enia si di alayẹ ọkàn, enia jẹ ọkàn kan. Otitọ ni Bibeli sọ! On ni ọla-aṣẹ lori ohun ti ọkàn enia jẹ. Awọn keferi onimọ ijinlẹ igbánì, ti ko ni Ọrọ Ọlọrun ti a kọwe rẹ̀ silẹ, li awọn ẹniti o wipe enia ní ninu rẹ̀ ọkàn ẹmi kan ti a ko le fojuri ti o pada si ilẹ ọba ẹmi nigbati ara enia ba kú. Ninu ede Heberu ọrọ na fun “ọkàn” ni neph’esh; ninu Griki Septuagint Version ti Iwe Mimọ Heberu o jẹ psy-’khe’. Nipa bayi, ohun ti o ṣẹlẹ si ara enia ṣẹlẹ si ọkàn enia. Ki iṣe ara enia li o kú, kaka bẹ̀, gẹgẹ bi Jehofah Ọlọrun ti wi ninu Esekieli 18:4: “Kiyesi i, gbogbo ọkàn ni t’emi; . . . Ọkàn ti o ba ṣẹ̀, on o kú.” (Pẹlu, ẹsẹ 20)
24. Eṣe ti “ara iyara” fi yatọ si “ara ti ẹmi”?
24 Enia ki iṣe ti ẹmi, ẹni ti ẹmi. Ti ilẹ aiye li enia, ẹni ilẹ aiye: “[Jehofah] Ọlọrun si fi erupẹ ilẹ mọ enia.” (Genesisi 2:7) Ara ti Ọlọrun dá fun enia jẹ apapọ awọn nkan tin-tin-tin ti a mu lati inu ilẹ wa ati afẹfẹ. Ki iṣe ara ti ẹmi, a ko si le sọ ọ di ti ẹmi ki o ba le di alaiṣe fojuri ki o si má gbe ilẹ ọba ti ẹmi. O jẹ ara iyara, ti o yatọ ti a si yasọtọ patapata kuro ninu ara ti ẹmi gẹgẹ bi eyiti “awọn ọmọ Ọlọrun” ní li ọrun. Gẹgẹ bi alalaye lori Bibeli ti wi li ọgọrun ọdun kini C.E. pe: “Bi ara iyara ba mbẹ, ara ẹmi si mbẹ.” Awọn ara mejeji li a ko gbọdọ darupọ, Bibeli ko si da wọn ru pọ mọ ara wọn.—1 Korinti 15:44.
25. Kini Ọlọrun mí sinu iho imu enia lati sọ ọ di “aláyé ọkàn,” nì iyatọ si ẹkọ Griki?
25 Ihoho ara enia ti Ọlọrun fi erupẹ ilẹ mọ nibẹ ninu Paradise Igbadun jẹ pipe, ko si si eyiti o sọnu ninu awọn apakan tabi awọn ẹya ara rẹ̀. “Pipe ni iṣẹ rẹ̀; nitoripe idajọ ni gbogbo ọna rẹ̀.” (Deuteronomi 32:4) “Kiyesi i, eyi nikanṣoṣo ni mo ri,” ni ọlọgbọn Ọba Solomoni wi, “pe Ọlọrun ti dá enia ni iduroṣinṣin.” (Oniwasu 7:29) Lati mu ki ara enia akọkọ na waláyé ki o si má ṣiṣẹ daradara, Ọlọrun ko mu wá lati ọrun “ọkàn” (psy-khe) * alailẹmi eyiti, gẹgẹ bi ero keferi Griki, o njù kakiri bi labalàbà, ki o si mí i sinu tabi kì i bọ inu ara alailẹmi na. Ọlọrun mí sinu ara na ki iṣe iṣàn afẹfẹ kan lasan lati mu ki awọn ẹdọ foro ara na ki o fẹ̀. Ki iṣe ohun kan ti o dabi imupadabọ si iye lọna ifẹnukonu bi ti ẹnikan ti o ti mu omi yo. Ohun ti Ọlọrun mí sinu iho imu ara na li a npe ni “emi iye,” eyiti ki iṣe pe o kún ẹdọ foro na nikan ni pẹlu afẹfẹ ṣugbọn pẹlu o fi agbara iwaláyè sinu ara na eyiti a mu duro nipasẹ emi. Li ọna bayi “enia si di aláyè ọkàn.”
26. Eṣe ti a fi pe ọkunrin ekini ni Adamu, bawo li Ọlọrun si ṣe fi ete gidi sinu igbesi aiye rẹ̀?
26 Jehofah Ọlọrun di Baba na, Olufunni ni iye, fun ọkan enia akọkọ yi. Awọn ohun-elo fun mimọ ara enia na li a mu wa lati inu ilẹ, eyiti, li ede Heberu, a npe ni a-da-mah’, nitorina alayẹ̀ ọkàn yi li a pe bi o ti tọ́ gan ni Adamu. (Genesisi 5:1, 2) Baba ọrun na ní ete kan ni fifi ọmọ rẹ̀ ti ori ilẹ aiye sinu Paradise Edeni, O si fi ete sinu igbesi aiye Adamu. Nitori eyi a kà ninu Genesisi 9:15 pe: “[Jehofah] Ọlọrun si mu ọkunrin na, o si fi i sinu ọgba Edeni lati má ro o, ati lati ma ṣọ́ ọ.” Ọlọrun yàn fun Adamu iṣẹ rẹ̀ gẹgẹ bi olutọju-Paradise, aṣọgba. Lati fun wa ni ero ohun ti o ṣẹlẹ ninu Paradise ilẹ aiye na, a sọ fun wa pe: “[Jehofah] Ọlọrun si gbin ọgba kan niha ila orùn . . . Lati inu ilẹ [a-da-mah] ni [Jehofah] Ọlọrun mu onirúiru igi hù jade wa, ti o dara ni wiwò, ti o si dara fun onjẹ; igi iye pẹlu lárin ọgba na, ati igi imọ rere ati buburu.” (Genesisi 2:8, 9) Pẹlu oniruru “igi ti o dara ni wiwò,” ọgba Edeni ti nilati: jẹ ibi ẹlẹwa kan. Lara awọn igi rẹ̀ ti o si “dara fun onjẹ” ni igi ọpọtọ.
27. Bawo li Ọlọrun ṣe ri si i pe Adamu ko nikan wa ninu Paradise na ati pe o di ojulumọ awọn nkan?
27 Afi kiki Ọlọrun onifẹ nikan li o le fi Paradise Igbadun fun ọmọ rẹ̀ ori ilẹ aiye gẹgẹ bi ile rẹ̀, eyiti o darajulọ ti ilẹ aiye ni lati pese. Nitoripe o jẹ ẹni pipe, Adamu le ni imọriri pipe fun ọgba yi ati ẹwa rẹ̀. Ki iṣe on nikan li o wà nibẹ. Awọn ẹja oniríiru wà li odo ti o nṣan jade lati inu ọgba na ti o si pinya si awọn agbegbe miran rekọja álà ọgba na. (Genesisi 2:10-14) Oniruru awọn ẹiyẹ si wà pẹlu, ati awọn ẹranko ti nrako lori ilẹ, eyiti ngbe ile ati ti oko. Ọlọrun ri si i wipe Adamu mọ awọn ẹda orilẹ aiye wọnyi ti nwọn jẹ ti ẹda ti o rẹlẹ.
“Lati inu ilẹ ni [Jehofah] Ọlọrun si ti dá ẹranko igbẹ gbogbo, ati ẹiyẹ oju ọrun gbogbo; o si mu wọn tọ̀ Adamu wá lati wo orukọ ti yio sọ wọn; orukọ-korukọ ti Adamu si sọ olukuluku ẹda aláyé [neph’esh], on li orukọ rẹ̀. Adamu sì sọ ẹran-ọsin gbogbo ati ẹiyẹ oju-ọrun, ati ẹranko igbẹ gbogbo, li orukọ; Ṣugbọn fun Adamu a ko ri oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u.”—Genesisi 2:19, 20.
28. Nigbati o ri inaki, eṣe ti Adamu ko ni imọlara ibatan kankan pẹlu rẹ̀?
28 Bi a ti nfi awọn ẹranko igbẹ na han Adamu, ẹda alapa-gigun abirun gaùn-gaùn kan farahan. Adamu pè e ni qoph, eyiti o tumọsi “inaki” fun wa loni. (1 Awọn Ọba 10:22; 2 Kronika 9:21) Nigbati Adamu ri inaki yi, on ko ni imọlara ibatan kan pẹlu rẹ̀. On ko gbagbọ pe ẹjẹ rẹ̀ li a fi bi on. On ko kigbe jade pẹlu idunnu pe: “Eyiyi li egungun ninu egungun mi, ati ẹran-ara ninu ẹran-ara mi.” Isọfunni ti Adamu ri gba lati ọdọ Ọlọrun ni pe a ti da qoph (inaki) na tẹlẹ ni “ọjọ” iṣẹda kẹfa, ati pe, on Adamu, li Ọlọrun dá lọtọ laisi isopọ kankan nipa ti ara pẹlu inaki tabi eyikeyi miran ninu awọn ẹda rirẹlẹ lori ilẹ aiye. Adamu mọ pe iru ẹran-ara mẹrin li o wà. Gẹgẹ bia ti sọ ọ ni ọgọrun ọdun mọkandinlogun sẹhin, ni ibamu pẹlu awari ọgbọn ijinlẹ ti a ṣẹṣẹ ṣe: “Gbogbo ẹran-ara ki iṣe ẹran-ara kanna, ṣugbọn ọtọ li ẹran-ara ti enia, ọtọ li ẹran-ara ti ẹranko, ọtọ ni ti ẹja, ọtọ si ni ti ẹiyẹ.” (1 Korinti 15:39) Bẹkọ, biotilẹjẹpe Ọrọ Ọlọrun sọrọ nipa qoph (inaki) gẹgẹ bi “aláyé ọkàn” kan, a ko ri inaki lati “dabi” Adamu ki o si yẹ gẹgẹ bi ẹnikeji rẹ̀.—Genesisi 2:20.
29. Eṣe ti Adamu ko fọrọwerọ pẹlu ejo tabi jọsin fun ẹranko eyikeyi?
29 Bi Adamu ti nwo gbogbo awọn ẹranko igbẹ, nibẹ lori ilẹ tabi lori igi ni ẹranko kan wà ti o ni ìpẹ́ lara ti o nfà, laisi ọwọ. Adamu pe e ni na-hhash’, eyiti o tumọsi “ejo” fun wa. On ko bẹrẹ ifọrọwerọ- pẹlu Adamu, bẹni Adamu funrarẹ̀ ko si ba a sọrọ. On jẹ ẹda ti ko le sọrọ, afi kikún nikan li o nkùn. Adamu ko bẹru rẹ̀ tabi awọn ẹranko miran. On ko sin eyikeyi ninu wọn gẹgẹ bi ohun mimọ, ki tilẹ iṣe malu pápa. Ọlọrun rẹ ti fi wọn sabẹ rẹ̀, nitoripe on jẹ ọmọ Ọlọrun lori ilẹ aiye, ti a dá li aworan Ọlọrun ati ni ìrí Ọlọrun. Nitorina kiki Baba rẹ̀ ti mbẹ li ọrun, “Ọlọrun otitọ na,” Jehofah, li on nsìn.
ṢIṢEṢE IYE AINIPẸKUN LORI ILẸ AIYE
30, 31. (a) Bawo li Adamu yio ti walayè pẹ to, ati nibo? (b) Laisi aiṣododo, idanwo igbọran wo li Ọlọrun mu wa fun Adamu?
30 Bawo li a ṣe pete fun Adamu lati waláyè pẹ to, ati nibo? Ki iṣe ero Ọlọrun pe Adamu nilati ku ki o
si fi Paradise Edeni silẹ laibikita fun u. A ko nilati fi ilẹ aiye silẹ laisi olugbe. Ọlọrun fi lelẹ niwaju Adamu anfani fun iye aiyeraiye lori ilẹ aiye ninu Paradise Edeni. Ṣugbọn, eyiyi simi le igbọran aiyeraiye Adamu si Ọlọrun ati Ẹlẹda rẹ̀. Ọlọrun ko fi awọn itẹsi Kankan fun aigbọran, ko si itẹsi kankan fun ẹṣẹ ninu Adamu. Ọlọrun fifun ọmọ rẹ̀ ori ilẹ aiye awọn animọ Ọlọrun ti idajọ ododo, ọgbọn, agbara ati ifẹ, pẹlu ọgbọn iwarere pipe. Ṣugbọn, ni fifi jijẹ ọba alaṣẹ Rẹ han lori gbogbo agbaiye, o tọ́ fun Ọlọrun, laisi ifura eyikeyi si Adamu, lati dán ọmọ Rẹ̀ ori ilẹ aiye yi wò. Idanwo ti on mu wa sori Adamu jẹ didin ominira rẹ̀ kù lọna kekere gan. A ka pe:31 “[Jehofah] Ọlọrun si fi aṣẹ fun ọkunrin na pe, Ninu gbogbo igi ọgba ni ki iwọ ki o má jẹ: ṣugbọn ninu igi imọ rere ati buburu nì, iwọ ko gbọdọ jẹ ninu rẹ̀ nitoripe li ọjọ ti iwọ ba jẹ ninu rẹ̀ kiku ni iwọ o ku.”—Genesisi 2:16, 17.
32. Jijẹ eso igi imọ rere ati buburu ha iṣe koṣemani fun Adamu ki on ba le gbadun iye aiyeraiye bi?
32 Nihin li Olufunni-ni-Iye nla na fi lelẹ niwaju Adamu ọmọ rẹ̀ ireti iye aiyeraiye tabi iku aiyeraiye. Aigbọran si Ọlọrun Baba rẹ̀ ti mbẹ li ọrun yio yọrisi iku titilai fun Adamu laisi aniani. Igbọran onifẹ bi ti ọmọ kan si baba rẹ̀ yio yọrisi iye aiyeraiye. Ere fun igbọran titi lọ ko ni tumọsi iṣipopada Adamu si ọrun, nitoripe a ko da Adamu fun iye ninu ọrun pẹlu awọn angeli, ṣugbọn a pete rẹ̀ fun iye aiyeraiye ninu Paradise Igbadun ilẹ aiye. “Ọrun ani ọrun ni ti [Jehofah], ṣugbọn aiye li o fifun awọn ọmọ enia.” (Orin Dafidi 115:16) Jijẹ ti Adamu jẹ igi imọ rere ati buburu ki iṣe koṣemani fun wiwaláyè rẹ̀ titi lai, bikoṣe “igi iye” ti mbẹ larin ọgba na li o jẹ koṣemani.—Genesisi 3:22.
33. Pẹlu ẹri, kini ero Ọlọrun fun gbolohun ọrọ na “li ọjọ ti iwọ ba jẹ,” esitiṣe?
33 Biotiwukiori, bawo ni Adamu yio ti loye gbolohun ọrọ na “li ọjọ ti iwọ ba jẹ ninu rẹ̀” si? On ko ni idi tabi ipilẹ fun rironu nipa ọjọ kan ẹlegbẹrun ọdun, gẹgẹ bi ọrọ ti woli Mose sọ si Jehofah Ọlọrun nigba pipẹ pupọ lẹhinna pe: “Ẹgbẹrun ọdun . . . li oju rẹ, bi àná Orin Dafidi 90:4 ati akọle) Dajudaju on ko yonu pe: ‘O dara, bi emi ba ṣaigbọran ti mo si nilati ku, emi le ni pupọ tabi eyiti o pọ julọ ninu ọjọ ẹlẹgbẹrun ọdun na ti emi yio fi waláyé; eyini ko si ni buru ju.’ Adamu ko ni ipilẹ fun rironu ni iru ọna bẹ. On ti nilati loye lilo ti Ọlọrun lo ọrọ na “ọjọ” lati tumọsi ọjọ kan oni-wakati mẹrinlelogun. Dajudaju niwọnbi Ọlọrun ti sọrọ ni ibamu pẹlu agbara ọmọ rẹ̀ ori ilẹ aiye lati loye, nigbana, o ṣe dede pe, Ọlọrun ti nilati ni ọjọ oni-wakati mẹrinlelogun lọkan. On ko ni lọkan pe, “Ni ọjọ ẹlẹgbẹrun ọdun ti iwọ ba jẹ ninu eso igi imọ rere ati buburu ni iwọ yio ku.” Iru itumọ bẹ yio dín agbara ikilọ Ọlọrun kù.
li o ri.” (34. Bawo ni Adamu ṣe ri aṣẹ na gba nipa eso igi ti a kaléwòọ, bawo ni Adamu iba si ti gbadun ibatan timọtimọ pẹlu Ọlọrun to?
34 Adamu ri ikilọ alagbara yi gba lati ọdọ Ọlọrun táràtà, bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun le ti ba Adamu sọrọ nipasẹ angeli kan ti a ko fojuri. O jẹ ọrọ Ọlọrun, iṣẹ Ọlọrun. Ọlọrun ba Adamu sọrọ lati inu airi. On ko lo awọn ẹranko rirẹlẹ kan ti a dá, bi ejo kan, nipasẹ eyiti on le fi aṣẹ rẹ̀ ranṣẹ si Adamu ọmọ rẹ̀ ori ilẹ aiye. Ninu ọran ti eyiti a sọ kẹhin yi, ẹranko ti a dá yi li a le ti lo lẹhinna gẹgẹ bi ami kan fun Ọlọrun ki a si ba a lo gẹgẹ bi ohun mimọ, pẹlu ọ̀wọ̀ ti o yẹ. Ọlọrun otitọ na ko fẹ ijọsin ti a ṣe si on nipasẹ ẹranko kan ti a dá. Adamu ninu Paradise Igbadun sìn Ọlọrun táràtà. Bi on ba mba a lọ tifẹtifẹ lati ṣe bẹ titi aiyeraiye, laisi aniani iru ibasọrọpọ bẹ pẹlu Ọlọrun yio má baa lọ titi aiyeraiye. Wo anfani ti yio jẹ fun Adamu lati tipa bayi wà ninu Paradise ilẹ aiye pẹlu Ọlọrun titilai!
[Awọn Alaye Isale Iwe]
^ ìpínrọ̀ 5 Wo “Lodisi Praàeas” ti Tertulliian. Nibẹ ninu Ori 7, o wipe: “Bẹ gẹgẹ li Ọmọ mọ̀ Baba, ti a nsọrọ nipa ara rẹ̀ funrarẹ̀, labẹ orukọ na Ọgbọn: ‘OLUWA ṣe ẹda mi gẹgẹ bi ibẹrẹ awọn ọna rẹ̀.’” Tun wo awọn alaye lori Owe 8:22 pẹlu lati ọwọ Justin Martyr, Irenaeus, Athenagoras, Theophilus ti Antioku, Clement ti Alexandria, Cyprian (The Treatises of), “De Principiis” ti Origen, Dionysius, ati Lactantius.
^ ìpínrọ̀ 22 Ni Spanish: “Formó, pues, el Señor Dios al hombre del lodo de la tierra, e inspiróle en el rostro un soplo o espíritu de vida, y quedó hecho el hombre viviente con alma racional.”
^ ìpínrọ̀ 25 Ọkan ninu awọn itumọ ọrọ Griki na psy·khe’ ni “labalaba tabi afopina.”—Wo Liddell ati Scott’s Greek-English Lexicon, Volume 2, oju iwe 2027, apa 2, VI. Ninu itan atọwọdọwọ Griki ati Romu, Psyche jẹ obirin ẹlẹwa kan ti o duro fun ọkàn ti ọlọrun Eros si fẹran.
[Ibeere]
APOTI
The Lord God formed man of the dust of the ground, and breathed into his nostrils the breath of life; and man became a living soul. 8 ¶ And the LORD God planted a garden
OLUWA Ọlọrun na mọ enia lati inu erupẹ ilẹ, o si mí emí iye si iho imu rẹ̀; enia si di alãyè ọkàn. 8 ¶ OLUWA Ọlọrun si gbin ọgba kan