Orilẹ-ede kan Ti O Wọ inu Majẹmu pẹlu Ọlọrun
Ori 9
Orilẹ-ede kan Ti O Wọ inu Majẹmu pẹlu Ọlọrun
1. Awọn orilẹ-ede loni ti kun fun ohun ti ara jù lati ṣeto adehun pẹlu tani?
NINU awọn ọran larin awọn orilẹ-ede o jẹ aṣa fun orilẹ-ede kan lati wọ̀ inu adehun kan pẹlu orilẹ-ede miran fun ijumọ-dábòbò tabi awọn ibatan alalafia tabi paṣipárọ awọn aṣa tabi awọn nkan miran. Awọn orilẹ-ede oṣelu kan le wọ̀ inu eto kan labẹ adehun kan, gẹgẹ bi iru ti, loni, Eto Adehun ni Ariwa Atlantic (North Atlantic Treaty Organization [NATO]), Eto Adehun ti Warsaw (Warsaw Treaty Organization [tabi, Warsaw Pact]), tabi Eto Adehun ni Gúsù-ila-orùn Asia (Southeast Asia Treaty Organization [SEATO]), Ṣugbọn ilẹ tabi orilẹ-ede iṣelu wo loni li o wà ninu adehun pẹlu Ọlọrun? Loni awọn orilẹ-ede ti jẹ olufẹ ohun ti ara jù lati le ṣe eto adehun pẹlu Ẹni-ọrun kan ti a ko le fi oju ri gẹgẹ bi ẹnikeji ninu adehun na.
2. Awọn ibere wo li awa nfẹ ki a dahun nipa orilẹ-ede kan ti o wọ inu majẹmu pẹlu Ọlọrun?
2 Biotiwukiori, nigba lailai, orilẹ-ede gidi kan wà ti o waláyé lori ilẹ aiye ti o wọ̀ inu majẹmu pẹlu Ọlọrun Ọga Ogo Julọ li ọrun. Eyiyi tumọsi majẹmu pẹlu ẹgbẹ kan li ori ilẹ aiye ati ti ẹgbẹ kan li ọrun, ẹgbẹ kan ti a le fi oju ri ati ẹgbẹ kan ti a ko le fi oju ri. Gbogbo majẹmu li o ni ete ti a kede. Kini ete majẹmu pataki na lárin orilẹ-ede kan lori ilẹ aiye ati Ọlọrun otitọ ti mbẹ láyé li ọrun? Bawo li a ṣe ṣe iru majẹmu bẹ ti o dabi ẹnipe ko baramu? Awọn wọnyi li awọn ibere ti a fẹ dahun nisisiyi.
3. Tani yio jẹ ẹniti o yẹ julọ lati ṣeto fun awọn ọrọ, alarina, awọn ipo ati akoko iru majẹmu bẹ?
3 Ni jijẹ ọlọgbọn-gbogbo ati alagbara-gbogbo, Ọlọrun Ọga Ogo Julọ yio jẹ Ẹni na ti o yẹ lati nawọ tabi pete pápa iru majẹmu bẹ pẹlu orilẹ-ede awọn enia
alaipe, ẹlẹṣẹ. Labẹ awọn ipo nkan, yio ṣe dede fun lati sọ ete majẹmu na ati lati sọ awọn ohun ti o jẹmọ ọ ati lati yan onilaja kan lati ṣiṣẹ lárin Rẹ̀ ati awọn enia. On yio fi awọn ipo lelẹ lori eyiti majẹmu na yio má ba a lọ ki o si yàn akoko na pẹlu fun gbigbe majẹmu kan tabi adehun kalẹ. Akoko ti Ọlọrun yan tipẹtipẹ ṣáju jẹ ninu ọgọrun ọdun kẹrindinlogun ṣáju Sanmani Igba tiwa (tabi B.C.E.).4. Ni akoko dida majẹmu kan lọna aṣa pẹlu Abrahamu lori irubọ, iru akoko igba wo li Ọlọrun sọtẹlẹ fun iru-ọmọ rẹ̀?
4 Ọlọrun ti ṣe majẹmu kan bi aṣa lori ẹbọ riru pẹlu babanla gbogbo orilẹ-ede yi ti a nilati mu wá sinu majẹmu orilẹ-ede laipẹ. O jẹ lẹhinti Melkisedeki, ọba Salemu alufa Ọlọrun Ọga Ogo Julọ, kede ibukun sori Abrahamu ti o ja ajaṣẹgun ti ologun ni Ọlọrun to mu Abrahamu wọ̀ inu majẹmu ti a ṣe bi aṣa yi pẹlu Rẹ̀ lori ẹbọ riru. Nigbati o nfun Abrahamu ni idaniloju ti o lagbara pe ileri atọrunwa na li ao muṣẹ lori awọn atọmọdọmọ Abrahamu, Ọlọrun wi fun u pe: ‘‘Mọ̀ nitotọ pe iru-ọmọ rẹ yio ṣe alejo ni ilẹ ti ki iṣe ti wọn, nwọn o si sìn wọn, nwọn o si jẹ wọn ni ìyà ni irinwo ọdun; ati orilẹ-ede na pẹlu ti nwọn o má sìn, li emi o dá lẹjọ: lẹhinna ni nwọn o si jade ti awọn ti ọrẹ pipọ. Iwọ o si tọ̀ baba rẹ lọ li alafia; li ogbologbo ọjọ li a o sin ọ. Ṣugbọn ni iran kẹrin, nwọn o si tun pada wa nihinyi: nitori ẹṣẹ awọn ara Amori ko ti kún.’‘—Genesisi 15:13-16.
5. Akoko gigun ti o nilati kọjalọ ki iru-ọmọ Abrahamu to gba Ilẹ Ileri fi aye silẹ fun kini lati ṣẹlẹ?
5 Nipa bayi gbigba ti iru-ọmọ Abrahamu nipa ti ara gba ilẹ na li a fawọ rẹ̀ sẹhin si eyiti o ju irinwo ọdun lọ. Akoko gigun yi yio fi aye silẹ fun iru-ọmọ Abrahamu ti a yan nipa ti ara lati pọ si i di enia ti o ni memba pupọ, ti o pọ to lati lé awọn ara Amori ti ngbe ilẹ Kenaani jade ti nwọn nburu si i ninu ‘‘ẹṣẹ’‘ awọn ọna ibọriṣa wọn. Biotilẹjẹpe iru-ọmọ Abrahamu nipa ti ara yio dagba di enia ti o pọ si i ni iye lọpọlọpọ ni ilẹ ti o ṣajeji si ilẹ Kenaani, sibẹ Ọlọrun yio pa ilẹ na mọ dè wọn titi ’’ẹṣẹ’‘ awọn olugbe ilẹ na yio fi buru tobẹ ti nwọn fi yẹ fun lile kuro lori ilẹ na. Pe Ọlọrun yio fi agbegbe na fun iru-ọmọ Abrahamu nipa ti ara li akoko ti o yẹ fun u, ni Jehofah nisisiyi mu daniloju pẹlu majẹmu ti a ṣe bi aṣa.
“Li ọjọ na gán ni [Jehofah] ba Abramu da majẹmu pe: ‘iru-ọmọ rẹ ni mo fi ilẹ yi fun, lati ọdọ Egipti wá, titi o fi de odo nla nì, odo Euferate. Awọn enia Keni, ati awọn enia Kenissi, ati awọn enia Kadmoni, ati awọn enia Hitti, ati awọn enia Perissi, ati awọn Refaimu, ati awọn enia Amori, ati awọn enia Kenaani, ati awọn Girgaṣi, ati awọn Jebusi.’”—Genesisi 15:18-21.
6. Majẹmu orilẹ-ede yio ha fagile Ileri Abrahamu, ete wo ni yio si ṣiṣẹ fun niti awọn atọmọdọmọ Abrahamu?
6 Ni iyatọ si majẹmu atọrunwa na pẹlu ẹnikan, Abrahamu, majẹmu ti Ọlọrun ní li ọkàn nilati jẹ pẹlu orilẹ-ede nla kan ti atọmọdọmọ Abrahamu nipasẹ ila idile ti a yàn. Majẹmu orilẹ-ede na li a nilati fikun Ileri Abrahamu, eyiti o bẹrẹsi ṣiṣẹ nigbati Abrahamu rekọja Odo Euferate si ariwa ti o si wọ̀ agbegbe ti o wà ninu awọn álà ilẹ ti Ọlọrun sọ ninu majẹmu rẹ̀ ti o ṣe bi aṣa pẹlu Abrahamu lori ẹbọ riru. (Genesisi 12:1-7) Ṣiṣe majẹmu na pẹlu orilẹ-ede atọmọdọmọ Abrahamu ko fagile Ileri Abrahamu ṣugbọn a wulẹ fikun u ni. Pẹlu ọgbọn bẹ gẹgẹ, nitoripe ki iṣe gbogbo atọmọdọmọ Abrahamu nipa ti ara ni yio fi ara han bi ẹni yiyẹ lati ṣe alabapin ninu Ileri Abrahamu niti imuṣẹ rẹ̀ fun bibukun gbogbo orilẹ-ede aiye ati idile. Nitorina, majẹmu orilẹ-ede ti a fikun u yio ṣiṣẹ daradara gẹgẹ bi iranlọwọ kan tabi ọna kan lati mura awọn ti o yẹ silẹ lati tẹwọgba ati lati fi totọtotọ tẹle Messiah tôtọ na lẹhin, ‘‘iru-ọmọ’‘ ’’obirin’‘ Ọlọrun li ọrun ti a ṣeleri na, nigbati Ọlọrun ran ti o si fi ami ororo yan ẹni yi.
7. Fun awọn idi wo ni Ọlọrun ko fi ni pari majẹmu na pẹlu awọn atọmọdọmọ Abrahamu ṣáju opin irinwo ọdun wọnni?
7 Ṣiṣe afikun majẹmu orilẹ-ede na ko ni ṣẹlẹ ṣáju irekọja eyiti o ju irinwo ọdun lọ lati igbati Ọlọrun ti pari majẹmu yi pẹlu Abrahamu lori riru ẹbọ, nitoripe li akoko na Abrahamu ko ni iru-ọmọ kankan lati ọdọ Sara aya rẹ̀ ti o yàgàn. Siwaju si i, Ọlọrun ko ni ṣe majẹmu kan pẹlu awọn atọmọdọmọ Abrahamu kankan nigbati nwọn wà li oko ẹru tí orilẹ-ede ajeji si npọn wọn loju. Ni pataki li eyi ri bẹ, nigbati dida Eksodu 8:25-27) Lakọkọ lẹhinti Ọlọrun ti dajọ lile fun orilẹ-ede a-pọn-ni-loju ti o si gba awọn enia rẹ̀ là ti o si sọ wọn di ominira lati wọ̀ inu majẹmu kan pẹlu Rẹ̀, ni Ọlọrun to gbe majẹmu kan kalẹ pẹlu wọn. Eyiyi yio jẹ li opin ‘‘irinwo ọdun’‘ ti a sọtẹlẹ. Nipa bayi a ṣakiyesi pe Jehofah Ọlọrun ti samisi awọn akoko rẹ̀ funrarẹ̀ fun ṣiṣe iṣẹ ’’ete aiyeraiye’‘ rẹ̀ niti Ẹni Ami ororo, Messiah.
majẹmu ná nbere fun iru awọn ẹbọ ti o jẹ irira ati ilodisi fun awọn orilẹ-ede ti npọn wọn loju ti o si nmu wọn sinru. (8, 9. (a) Iru igba akoko wo li o bẹrẹ nigbati a gba Isaaki kuro li ẹnu ọmu, bawo si ni? (b) Opin akoko na jẹ akoko fun kini niti iru-ọmọ Abrahamu nipa ti ara?
8 Ọdun marundinlọgbọn lẹhinti Abrahamu wọ: Ilẹ Ileri na, tabi nigbati o di ọmọ ọgọrun ọdun, o di baba fun ọmọkunrin rẹ̀ kanṣoṣo nipasẹ Sarah, aya rẹ̀, ṣugbọn o, eyiyi jẹ iṣẹ iyanu atọrunwa. Eyiyi jẹ ni ilẹ ti koiti di ti Abrahamu sibẹ tabi ti ọmọ rẹ̀ Isaaki. O jẹ nigbati a gba ọmú li ẹnu Isaaki ni ipọnni-loju na bẹrẹ lori ‘‘iru-ọmọ’‘ nipa ti ara na nipasẹ ẹniti Messiah na yio gba de. Eyi jẹ nigbati Iṣmaeli ẹni ọdun mọkandinlogun ọmọ-baba Isaaki bẹrẹsi fi Isaaki ti a ṣẹṣẹ já li ẹnu ọmú ṣe yẹyẹ laiyẹ. Iru iwa bẹ ti o fi owú jijẹ han le yọrisi jamba kan fun iwaláyé Isaaki, ajogun ti Ọlọrun fifun Abrahamu.—Genesisi 16:11, 12.
9 Gẹgẹ bi iṣiro akọkọ ti fihan, ibẹrẹ pipọn ‘‘iru-ọmọ’‘ Abrahamu loju ni ilẹ kan ti ki iṣe tiwọn ṣẹlẹ nigbati Abrahamu di ẹni ọdun marundinladọfa ti Isaaki si jẹ ẹni ọdun marun. Eyini ṣẹlẹ ni ọdun 1913 B.C.E. (Genesisi 21:1-9; Galatia 4:29) Bẹ gẹgẹ, ‘‘irinwo ọdun’‘ ipọnni- loju na lori ‘‘iru-ọmọ! Abrahamu nipa ti ara yio dopin ni 1513 B.C.E. Eyini yio jẹ ọdun fun iru-ọmọ Abrahamu lati jade kuro ni ilẹ orilẹ-ede apọnni-loju ki o si bẹrẹsi pada lọ si ilẹ awọn babanla rẹ̀, Ilẹ Ileri na. Eyini li akoko ti o yẹ fun Ọlọrun lati gbe majẹmu orilẹ-ede kalẹ pẹlu ‘‘iru-ọmọ’‘ Abrahamu, ki on ba le mu wọn wá si Ilẹ Ileri na gẹgẹ bi orilẹ-ede kan ninu majẹmu kan ti o dè wọn pẹlu Rẹ̀. Akoko na fun eyi, lí opin irinwo ọdun, si tun jẹ irinwo ọdun o le ọgbọn lẹhinti Abrahamu ti rekọja Odo Euferate ti Ileri Abrahamu si bẹrẹsi ṣiṣẹ.—Eksodu 12:40-42:; Galatia 3:17-19.
IGBEKALẸ MAJẸMU ORILẸ-EDE KAN
10. De aye ipo wo ni iru-ọmọ Abrahamu dagba ni Egipti, ṣugbọn nikẹhin labẹ ipo Wo?
10 Lati igbati Jakobu ọmọ-ọmọ Abrahamu ti dide pẹlu idile rẹ̀ kuro ni ilẹ Kenaani, ati titi lọ de opin irinwo ọdun, awọn atọmọdọmọ Jakobu, awọn ẹya Israeli mejila, ba ara wọn ni ilẹ Egipti ti iṣe ti Hamu (ki iṣe Egipti ti Arabu, bi o ti ri li oni). Gẹgẹ bi Jehofah Ọlọrun ti sọtẹlẹ, ipọnju ti de sori ‘‘iru-ọmọ’‘ Abrahamu nipa ti ara o si ti di lile koko nisisiyi. Ete eyi ni lati pa awọn enia Abrahamu, ọrẹ Ọlọrun, rẹ̀ kuro. Laibikita fun eyi, nwọn ti pọ si i lati dabi awọn irawọ oju ọrun ati bi yanrin eti okun, lainiye, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣeleri. Nikẹhin, o ṣéṣe fun wọn lati ko ‘‘iwọn ọgbọn ọkẹ ẹlẹsẹ ọkunrin’‘ jọ fun iṣẹ ogun. (Eksodu 12:37) Bẹkọ, Ọlọrun ko gbagbe majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu ọrẹ rẹ̀. O si tun fi akoko rẹ̀ ti o kede sọkan. Nitorina o mura tan fun iṣẹ li akoko ti o yẹ.
11. Tani Ọlọrun gbe dide lati jẹ aṣaju fun Israeli, bawo li ẹni yi si ti ṣe fi ara rẹ̀ han gẹgẹ bi aṣaju?
11 Tani gbọdọ jẹ aṣaju wọn ti a le fojuri nisisiyi? Ọlọrun ko yan olori ẹya Judah gẹgẹ bi ẹnipe eyini jẹ ọranyan nitori ibukun Ijọba eyiti Jakobu ti sure sori Judah. (Genesisi 49:10; 1 Kronika 5:1, 2) Kakabẹ, Ọlọrun Ọga Ogo Julọ, pẹlu ẹtọ rẹ̀ ti o jẹ tirẹ̀ lati yàn, yan ọkunrin ti o yẹ ni ẹya Lefi, Mose ọmọ-ọmọ ọmọ Lefi. (Eksodu 6:20; Numeri 26:58, 59) Ogoji ọdun ṣaju opin irinwo ọdun na, Mose pinnu lodisi gbigbe igbe aiye ni afin Farao ti Egipti o si dà ara rẹ̀ pọ mọ awọn ọmọ Israeli arakunrin rẹ̀ o si yọda ara rẹ̀ fun wọn gẹgẹ bi aṣaju wọn lati ko wọn jade kuro li oko ẹru. ‘‘O si ṣebí awọn ara on mọ bi Ọlọrun yio ti ti ọwọ on gbà wọn: ṣugbọn nwọn ko mọ̀.’‘ Nigbana Ọlọrun koiti ran Mose lati dá awọn enia rẹ̀ ti a ko lẹru silẹ. O di ọranyan fun Mose lati sa kuro ninu isapa Farao lati pa a. O sa si abẹ ábò ni ilẹ Midiani o gbeyawo o si di daran-daran fun baba iyawo rẹ̀.—Eksodu 2:11 titi de 3:1; Iṣe 7:23-29.
12. Nigbawo ati nibo ni Mose ti di ‘‘ẹni ami ororo’‘ Jehofah, pẹlu iṣẹ wo si ni?
12 Ogoji ọdun kọja, Mose si di ẹni ọgọrin ọdun. Lẹhinna nigbati Mose nṣọ́ agbo ẹran lẹba oke Sinai, angeli Ọlọrun ṣe ifarahan yiyanilẹnu fun Mose lẹba Oke Horebu, Eksodu 3:2-14) Nipa bayi Ọlọrun yan Mose gẹgẹ bi woli Rẹ̀ ati aṣoju, nisisiyi Mose le di ẹniti a pe ni ’ẹni ami ororo,’‘ tabi ‘‘messiah’‘ bi o ti tọ, bakanna gẹgẹ bi ti awọn babanla rẹ̀ Abrahamu, Isaaki ati Jakobu. (Orin Dafidi 105:15; Iṣe 7:30-35; Heberu 11:23-26) Jehofah fihan pe li Oke Horebu ni ibiti On yio mu awọn enia Mose wá sinu majẹmu kan pẹlu Rẹ̀, nitoripe Jehofah sọ wipe Mose yio mu wọn, jade kuro ni Egipti wá si oke yi, nibẹ lati sìn I.—Eksodu 3:12.
nkan bi igba ibusọ ni gusu ila orùn Suez Canal li ode oni. Nihin, ni Horebu, Jehofah Ọlọrun sọ orukọ rẹ̀ jade, ni lẹta kọkan, lọna apẹrẹ, fun Mose, pe: ‘‘Emi Ni Ẹniti O Wà ... Bayi ni ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Emi Ni li o ran mi si nyin.’‘ (13. Bawo Ji a ṣe mu Farao wa si koko pipa aṣẹ fun awọn ọmọ israeli lati jade kuro ni Egipti?
13 Nitori kikọ leralera ti Farao kọ̀ lati jẹki awọn ọmọ Israeli ki o lọ li ominira, Jehofah mu onirúiru awọn àrùn wá sori rẹ̀ ati awọn enia rẹ̀. Arun ikẹwa ti o si kẹhin li ọ̀kan ti o fọ́ ọkàn lile Farao ati atako rẹ̀ tútú. Árùn yi pa awọn akọbi awọn idile Egipti wọnni ati ti awọn ẹran-ọsin wọn. A dábòbò awọn ọmọ Israeli kuro lọwọ iku akọbi wọn nitoripe nwọn ṣe igbọran si Jehofah Ọlọrun nwọn si jẹ ase irekọja, ekini ti nwọn kọkọ ṣe, ninu ile wọn. Angeli amudajọ Jehofah ṣẹ, nigbati o ri ẹjẹ ọdọ agutan Irekọja ti a wọ́n sara atẹrigba awọn ile wọn, o ré wọn kọja, iku ko si wọ̀ inu agbo idile. Naṣoni baba Salmoni, ti ẹya Judah, li a pamọ láyè, pẹlu Nadabu, ọmọkunrin akọbi ẹgbọn Mose ọkunrin, Aaroni. Ṣugbọn akọbi ọmọkunrin Farao kú. Ninu ibanujẹ ati labẹ itẹpẹlẹmọ lati ọdọ awọn ara Egipti ti nṣọfọ, Farao paṣẹ pe ki awọn ọmọ Israeli ti ko hamọra ogun jade kuro ni ilẹ na.—Eksodu 5:1 si 12:51.
14. Igba akoko wo li o dopin ni ọjọ Irekọja ekini, kini Ọlọrun sì paṣẹ niti oru na?
14 Alẹ Irekọja pataki ti ọdun 1513 B.C.E. na mú wá si opin lẹsẹkanna iye awọn akoko kan ti a sami si. Irinwo ọdun pipọn iru-ọmọ Abrahamu nipa ti ara loju ni ilẹ kan ti ki iṣe tiwọn dopin. Igba ọdun o le marundinlogun gbigbe ni Egipti lati igba dide Jakobu babanla dopin. Irinwo ọdun o le ọgbọn lati igba ti Eksodu 12:40-42.
6Abrahamu rekọja Odo Euferate ti o si bẹrẹsi gbe ni Ilẹ Ileri dopin. Abajọ ti a fi kà pe: ‘‘Njẹ igba atipo awọn ọmọ Israeli ti nwọn ṣe ni ilẹ Egipti, o jẹ irinwo ọdun o le ọgbọn. O si ṣe li opin irinwo ọdun o le ọgbọn, ani li ọjọ na gan, li o si ṣe ti gbogbo ogun [Jehofah] jade kuro ni ilẹ Egipti. Oru ti o yẹ ki a kiyesi gidigidi ni si [Jehofah] ni mimu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti; eyi li oru ti a kiyesi si [Jehofah], li ati irandiran gbogbo awọn ọmọ Israeli.’‘—15. Bawo li Ọlọrun ṣe gba awọn ọmọ Israeli la kuro lọwọ awọn ara Egipti ti nlepa wọn, orin kini nwọn si kọ nigbana?
15 Gẹgẹ bi ọna ọgbọn ẹwẹ ogun kan, Jehofah nipasẹ Mose ṣamọna awọn enia rẹ̀ ti a danide lọ si ebute Okun Pupa li apa iwọ òrùn li oke. Ni rirò pe on ti dẹkùn mu awọn ọmọ Israeli, Farao ati awọn ọmọ ogun rẹ̀ lori kẹkẹ ati ẹṣin nlepa nwọn si sunmọ awọn ẹrú wọn ti nsalọ. Ṣugbọn Ọlọrun Olodumare mu ki ọna abajade kan ki o ṣi silẹ awọn ọmọ Israeli si kọja li oru lori ilẹ gbigbẹ lọ si Etikun Sinai. Nigbati a gba awọn ara Egipti li àyè lati sare wọ inu kọlọfin ibi isapamọsi, Ọlọrun mu ki awọn omi Okun Pupa ki o padabọ wa sori wọn o si rì wọn ati awọn ẹṣin wọn. Ọrọ Ọlọrun ko jakulẹ, pe On yio ṣe idajọ orilẹ-ede aninilara fun ‘‘iru-ọmọ’‘ Abrahamu nipa ti ara. (Genesisi 15:13, 14) Lábò li etikun Sinai, awọn ẹlẹri idajọ Jehofah kọrin pe: ‘‘[Jehofah] yio jọba lai ati lailai . . . Ẹ; kọrin si [Jehofah] nitoriti o pọ li ogo; ẹṣin ati ẹlẹṣin on li o bì ṣubu sinu okun.’‘—Eksodu 15:1-21.
16. Kini Ọlọrun pete fun Israeli ti o pagọ ni Horebu, ki si ni ete na lati igbana lọ?
16 O sami si ọjọ pataki kan nigbati awọn ọmọ Israeli de, ni oṣu kẹta ti oṣupa (Sifani) lẹhinti nwọn kuro ni Egipti, wá sinu aginju Sinai ti nwọn si tẹdo si ẹba ‘‘oke Ọlọrun,’‘ Horebu. Nibẹ ni Jehofah gbe sọ fun Mose pe nwọn nilati sìn on. (Eksodu 3:1, 12; 19:1) A kesi woli Mose nisisiyi lati ṣiṣẹ gẹgẹ bi onilaja lárin Ọlọrun ati awọn enia rẹ̀ ti o pagọ. Nisisiyi Jehofah pete majẹmu kan larin Rẹ̀ ati awọn enia na o si fi ete majẹmu na lelẹ. Fun Mose, ti o wà lori Oke Horebu, O wipe: ‘‘Bayi ni ki iwọ ki o sọ fun ile Jakobu, ki o si wi fun awọn ọmọ Israeli pe; Ẹnyin ti Pg 17rì ohun ti mo ti ṣe si awọn ara Egipti, ati bi mo ti rù nyin li apa iyẹ idì, ti mo si mu nyin tọ̀ ara mi wá. Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin ba fẹ gba ohun mi gbọ nitotọ, ti ẹ o si pa majẹmu mi mọ, nigbana li ẹnyin o jẹ iṣura fun mi ju gbogbo enia lọ: nitori gbogbo aiye ni ti emi. Ẹnyin o si má jẹ ijọba alufa fun mi, ati orilẹ-ede mimọ.’‘—Eksodu 19:3-6.
17. Itolẹsẹsẹ wo li o fihan boya Jehofah fi agbara mu majẹmu na wá sori awọn ọmọ Israeli ti a gbala?
17 Ọlọrun Ọga Ogo Julọ ko fi agbara mu awọn ọmọ Israeli wọ̀ inu majẹmu yi. O fi wọn silẹ li ominira lati yan boya nwọn yio wọ̀ inu majẹmu kan pẹlu rẹ̀ tabi bẹkọ, ani biotilẹjẹpe on lo gba wọn la kuro ni Egipti ati Okun Pupa. Ki nwọn jẹ ‘‘iṣura!’‘ fun Jehofah kẹ̀? Ki nwọn jẹ ‘‘ijọba alufa ati orilẹ-ede mimọ’‘ kan fun U? Bẹni, ohun ti awọn ọmọ Israeli nfẹ lati ṣe nhigbana li eyini. Nitorina, nigbati Mose sọ fun awọn ọkunrin aṣoju awọn enia na nipa majẹmu ti Ọlọrun pete, nigbana, gẹgẹ bi a ti ka a, ‘‘gbogbo awọn enia na si jumọ dahun, nwọn si wipe, Ohun gbogbo ti [Jehofah] wi li awa o ṣe.’‘ Nisisiyi Mose rohin ipinnu awọn enia na pada fun Jehofah, ẹniti o tẹsiwaju nigbana pẹlu gbigbe majẹmu na kalẹ gẹgẹ bi nwọn ti lọwọ si i.—Eksodu 19:7-9.
18. Ni ọjọ kẹta lẹhinna, kini Ọlọrun kede fun Israeli?
18 Li ọjọ kẹta lẹhinna Jehofah, nipasẹ angeli rẹ̀ lori Oke Sinai nibẹ ni Horebu, kede fun awọn ọmọ Israeli ti o pejọ awọn Ọrọ Mẹwa tabi Ofin Mẹwa. Awọn ofin wọnyi li a le kà funrawa ninu Eksodu 20: 2-17.
A SỌ ONILAJA TITOBIJU TẸLẸ
19. (a) Nitori iran nla na, kini awọn ọmọ Israeli bere lọwọ Mose? (b) Kini Mose wi ni idahun?
19 Akoko na jẹ pataki kan! ‘‘Gbogbo awọn enia na si ri àrá na, ati manamana na, ati ohùn ìpè na, nwọn ri oke na nṣe éfin nigbati awọn enia si ri i, nwọn gbọ̀n, nwọn duro li okérè réré. Nwọn si wi fun Mose pe, Iwọ ma ba wa sọrọ, awa o si gbọ: ṣugbọn máṣe jẹ ki Ọlọrun ki o ba wa sọrọ, ki awa ki o má ba ku.’‘ (Eksodu 20:18, 19) Idahun Ọlọrun si ohun ti awọn ọmọ Israeli ti ẹ̀rù mbà yi nfẹ li a ṣe akọsilẹ rẹ̀ ni kikun si i ninu Deuteronomi 18:14-19. Nibẹ, lẹhin sisọ fun awọn ọmọ Israeli pe Ọlọrun ko fun wọn ni awọn pidan-pidan ati awọn alafọṣẹ gẹgẹ bi alarina larin On ati awọn, Mose ntẹsiwaju lati wipe:
“Ṣugbọn bi o ṣe ti rẹ ni, [Jehofah] Ọlọrun rẹ ko gba fun ọ bẹ. IJehofah)l Ọlọrun rẹ yio gbe woli kan dide fun ọ lárin rẹ, ninu awọn arakunrin rẹ, bi emi; on ni ki ẹnyin ki o fetisi; Gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ bere lọwọ [Jehofah] Ọlọrun rẹ ni Horebu li ọjọ ajọ nì wipe, Maṣe jẹ ki emi tun gbọ ohun IJehofahJ Ọlọrun mi mọ, bẹni ki emi ki o má tun ri ina nla yi mọ; ki emi ki o má ba kú. [Jehofah] si wi fun mi pe, ‘Nwọn wi rere li eyiti nwọn sọ. Emi o gbe woli kan dide fun wọn larin awọn arakunrin wọn, bi iwọ; emi o si fi ọrọ mi si i li ẹnu, on o si sọ fun wọn gbogbo eyiti mo palaṣẹ. Yio si ṣe ẹniti ko ba fetisi ọrọ mi ti on o má sọ li orukọ mi, emi o bere lọwọ rẹ̀.’”
20, 21. (a) O ha rọrun fun Israeli lati gbagbọ pe woli miran ti o dabi Mose yio wà? (b) Li ọna wo ni woli ọjọ iwaju yi yio fi dabi Mose, lori ipilẹ wo si ni?
20 Woli kan bi Mose, ẹniti Ọlọrun ba sọrọ, lọna apẹrẹ ‘‘lojukoju’‘? O le ti ṣoro fun awọn ọmọ Israeli lati tẹwọgba iru ero bẹ, nigbati Mose funrarẹ̀ sọ fun wọn ohun ti Ọlọrun ti sọ. Sibẹ, eyini li ohun ti Ọlọrun Olodumare sọ pe on yio gbe dide fun awọn enia rẹ̀. ‘Bi Mose’ ko ni tumọsi didọgba pẹlu Mose lasan. Woli ti a ṣeleri na le dabi Mose, sibẹ ki o si tobiju Mose.
21 Lati ọdọ awọn woli Israeli lẹhin Mose ati titi lọ de ọdọ Malaki ko si woli kan ti o dabi Mose ko si si ọkan ti o tobiju Mose. (Deuteronomi 34:1-12) Ṣugbọn nipa ti Ẹni Ami ororo ti a ṣeleri na nkọ, Messiah na, ti yio jẹ ‘‘iru-ọmọ obirin’‘ Ọlọrun li ọrun? (Genesisi 3:15) Dajudaju Ọlọrun nsọrọ nipa ẹni yi nigbati, o sọrọ si Mose nipa woli bi Mose li ọjọ iwaju. Gẹgẹ bi Mose, Messiah ‘‘iru-ọmọ’‘ yi yio jẹ Onilaja kan lárin Ọlọrun ati enia, ṣugbọn o tobiju Mose. Dajudaju awọn olusin Ọlọrun otitọ ati aláyè nilati ni pupọ ti a ṣe fun wọn nisisiyi ju eyiti a ṣe fun awọn orilẹ-ede Israeli igbánì nipasẹ Mose. Nitorina Mose ṣapẹrẹ Woli Jehofah Titobiju ti mbọ wa.
22. Eṣe ti woli bi Mose ti mbọ yio fi lodi si lilo ere ninu ijọsin?
Eksodu 20:22, 23) Rekọja gbogbo ohun ti a le ṣè, eyiyi jẹ aṣẹ kan lodisi lilo awọn ere alailefọhun, alailẹmi, atọwọda ninu ijọsin Ọlọrun na ti o ti sọrọ lati ọrun wa funrarẹ̀. O tẹnumọ ọ gidigidi ohun ti Ọlọrun sọ ninu ekeji ninu awọn Ofin Mẹwa, gẹgẹ bi a ti sọ ọ ninu Eksodu 20:4-6. Woli Messiah na ti o dabi Mose yio lodisi lilo iru awọn ere isin bẹ.
22 Ni akoko na Jehofah Ọlọrun si tun sọ fun Mose pe: ‘‘Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin ri bi emi ti ba nyin sọrọ lati ọrun wá. Ẹnyin ko gbọdọ ṣe ọlọrun miran pẹlu mi; Enyin ko gbọdọ ṣe ọlọrun fadaka, tabi ọlọrun wura, fun ara nyin.’‘ (23. Eṣe ti a fi saba npe majẹmu pẹlu Israeli ni Majẹmu Ofin?
23 Ṣaju gbigbe majẹmu na kalẹ nipasẹ Mose onilaja rẹ̀, Ọlọrun fun u li awọn ofin miran ni afikun si awọn Ofin Mẹwa na. Awọn wọnyi li a kọ akọsilẹ rẹ̀ ninu Eksodu, ori kọkanlelogun titi de ikẹtalelogun. A kọ Wọn silẹ ninu iwe akajọ tabi ‘‘iwe’‘ kan, ti o wa lọwọ nigbati a nilati gbe majẹmu na kalẹ bi aṣa. Niwọnbi a ti nilati sami si majẹmu yi ni pataki nipasẹ fifunni ni ofin atọrunwa fun awọn enia Ọlọrun ti a yan lati pamọ, o jẹ majẹmu ofin a si saba má npẹé e ni Majẹmu Ofin. Akopọ ofin rẹ̀ tabi apapọ awọn ofin li ọna itolẹsẹsẹ ni Iwe Mimọ sọrọ gẹgẹ bi ‘‘Ofin.’‘
24. Bawo li o ti pẹ to lẹhin majẹmu pẹlu Abrahamu ki a to ṣe majẹmu Ofin, Ileri Abrahamu ha si ṣiṣẹ sibẹ?
24 Niwọnbi a ti fi Ofin majẹmu yi pẹlu Israeli han lọna Ofin Mẹwa ni nkan bi adọta tabi ọkanleladọta ọjọ lẹhin oru Irekọja ni Egipti, a le sọ ọ daradara pe ofin ‘‘de lẹhin ọgbọn-le-nirinwo ọdun lẹhin majẹmu Abrahamu ni 1943 B.C.E.].’‘ Fifun Israeli li Ofin na lẹhin iru akoko gigun bẹ ko sọ majẹmu ti a ba Abrahamu da di asan ‘‘ti à ba fi mu ileri na di alailagbara.’‘ (Galatia 3:17) Ileri Ọlọrun lati bukun gbogbo orilẹ-ede ati awọn idile aiye ninu ‘‘iru-ọmọ’‘ Abrahamu ṣì wà sibẹ. Ko ni kuna!
25. Tani majẹmu Ofin na dè, ati nipa lilo kini fun u?
25 Jẹki a ri i daju lati ṣakiyesi pe majẹmu Ofin pẹlu Israeli li a sọdi alagbara, ti o rọra dé awọn ẹgbẹ ti o Eksodu 24:6-8 sọ fun wa: ‘‘Mose gẹgẹ bi Alarina si mu ábòọ ẹjẹ na o si fi i sinu awokoto; ati ábọò ẹjẹ na o si fi wọn ara pẹpẹ na. O si mu iwe majẹmu ni, o si kà a li eti awọn enia: nwọn si wipe, Gbogbo eyiti [Jehofah] wi li awa o ṣe, awa o si gbọran. Mose si mu ẹjẹ na, o si wọ́n ọ sara awọn enia, o si wipe, Kiyesi ẹjẹ majẹmu, ti [Jehofah] ba nyin dá nipasẹ ọrọ gbogbo wọnyi.’—Ṣakiyesi Eksodu 24:3 pẹlu.
wà ninu majẹmu na, nipa lilo ẹjẹ awọn ohun irubọ. Akọsilẹ ti mbẹ ninu26. Kini duro fun lilo ẹjẹ lori pẹpẹ Ọlọrun, ki si ni ti wíwọ́n ẹjẹ si awọn enia lara?
26 Pẹpẹ ti Mose ti kọ lẹba Oke Sinai duro fun Jehofah Ọlọrun, ẹniti a ti ṣe awọn irubọ na si lori pẹpẹ yi. Nitorina, nipa lilo abọ ẹjẹ awọn ẹran irubọ na lori pẹpẹ na, Jehofah Ọlọrun li a mu wá sinu majẹmu na lọna apẹrẹ a si dà a mọ ọ gẹgẹ bi apakan rẹ̀. Lọna miran ẹwẹ, nipa fifi abò ẹjẹ irubọ na wọn awọn enia lara, awọn na pẹlu li a mu wa sinu majẹmu na gẹgẹ bi apa keji nibẹ a si rọra dé wọn mọ ọ lati mu awọn ohun ti a mbere wọnni ṣẹ eyiti o kàn wọn. Nipa bayi nipasẹ ẹjẹ na awọn ẹgbẹ mejeji, Ọlọrun ati orilẹ-ede Israeli, li a sopọ ninu majẹmu kan.
27. Kini, niti igbekalẹ majẹmu Ofin, fihan pe awọn ọmọ Israeli ko rin wọ̀ inu rẹ̀ laimọkan tabi labẹ ifipamuni?
27 Orilẹ-ede Israeli ko wọ̀ inu majẹmu yi laimọkan tabi labẹ ikimọlẹ ati ifipa-muniṣe. Ọjọ ti o ṣáju gbigbe majẹmu na kalẹ pẹlu ẹjẹ nwọn ti ni awọn ọrọ Ọlọrun ati ipinnu ti a sọ fun wọn nwọn si ti tẹwọgba awọn wọnyi. Gẹgẹ bi Eksodu 24:3 ti wi: ‘‘Mose si wá, o si sọ gbogbo ọrọ [Jehofah], ati gbogbo idajọ fun awọn enia: gbogbo enia si fi ohun kan dahun wipe, Gbogbo ọrọ ti [Jehofah] wi li awa o ṣe.’‘ Ọjọ keji, lẹhinti Mose ti kà ‘‘iwe majẹmu’‘ si etigbọ gbogbo enia, nwọn tun sọ itẹwọgba wọn jade fun Ofin Ọlọrun, lẹhin eyiti a fi ẹjẹ irubọ wọ́n wọn lara. Nisisiyi o di ọranyan fun gbogbo orilẹ-ede Israeli lati ṣe ohun ti Ọlọrun sọ nigbati O npete majẹmu na pe: ‘‘Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin ba fẹ gba ohùn mi gbọ nitotọ, ti ẹ o si pa majẹmu mi mọ, nigbana . . .’‘—Eksodu 19:5, 6.
28. Ẹgbẹ Wo ninu majẹmu Ofin na li a ṣiyemeji si niti iṣotitọ si awọn ọrọ rẹ̀, ati, lati jẹ mimọ, kini a mbere?
Malaki 3:6) Awọn ọmọ Israeli li a bere ibere lọwọ rẹ̀. Nwọn yio ha jẹ olôtọ si Ọlọrun ni ṣiṣe ohun ti nwọn fihan lati ṣe tifẹtifẹ? Nwọn yio ha wà lara awọn olótọ wọnni ti a nilati kojọpọ sọdọ Jehofah, ni imuṣẹ Orin Dafidi 50:4, 5: ‘‘Yio kọ si awọn ọrun lati oke wa, ati si aiye, ki o le ma ṣe idajọ awọn enia rẹ̀. Kó awọn enia mimọ mi jọ pọ sọdọ mi: awọn ti o fi ẹbọ ba mi dá majẹmu’‘? Ki iṣe gẹgẹ bi ẹnikọkan, ṣugbọn gẹgẹbi apapọ awọn enia, gẹgẹ bi orilẹ-ede kan, nwọn ti ṣe majẹmu Ofin yi lori awọn ẹbọ kan ti o wà fun gbogbo enia na. Nwọn yio ha fi ara wọn han lati jẹ ’’orilẹ-ede mimọ’‘? Lati ṣe eyi nwọn nilati takete si aiye yi.
28 A le reti pe Ọlọrun Olodumare nilati jẹ olotọ si apa ti Rẹ̀ ninu majẹmu ẹlẹ́gbẹ́ meji na, nitoripe On ki yipada. (29, 30. (a) Ihaṣe kiki wiwọ inu majẹmu Ofin lasan li a fi sọ Israeli di ‘‘ijọba alufa’‘ tabi kini eto fun awọn alufa? (b) Kini a sọ awọn ọkunrin ti o yẹ ninu awọn idile Lefi miran dà?
29 Kiki nitoripe nwọn wọ̀ inu majẹmu pẹlu Ọlọrun Ọga Ogo Julọ nwọn ki iṣe ‘‘ijọba alufa’‘ lẹsẹkẹsẹ. Lọnakọna nigbana nwọn ki iṣe ijọba kan ninu eyiti mẹmba ọkunrin kọkan jẹ alufa Ọlọrun fun gbogbo awọn orilẹ-ede miran ti mbẹ lori ilẹ aiye. Asọtẹlẹ Isaiah 61:6 li a koiti muṣẹ si wọn lara: ‘‘Ṣugbọn a o ma pè nyin ni alufa [Jehofah]: nwọn o má pè nyin ni Iranṣẹ Ọlọrun wa: ẹ o jẹ ọrọ̀ awọn keferi, ati ninu ogo wọn li ẹ o má ṣogo.’‘ Kakabẹ, gẹgẹ bi awọn ọrọ majẹmu Ofin na ti wi, awọn mẹmba ọkunrin ti o yẹ ninu kiki idile kanṣoṣo ni Israeli li a sọ di alufa, lati ṣiṣẹ fun gbogbo iyoku orilẹ-ede na. Eyiyi ni idile Aaroni, ẹgbọn Mose ọkunrin, ti ẹya Lefi. A sọ ọ di olori alufa Ọlọrun, a si sọ awọn ọmọ rẹ̀ di awọn alufa ọmọ-abẹ. Nitorina nwọn parapọ di oyè alufa Aaroni.
30 Awọn mẹmba ọkunrin ti o yẹ ninu gbogbo iyoku ẹya idile Lefi li a sọ di ojiṣẹ fun oye alufa Aaroni, lati ran wọn lọwọ ni bibojuto awọn iṣẹ isin wọn si ile Ọlọrun, tabi agọ ajọ, eyiti a bere fun ninu majẹmu Ofin.—Eksodu 27:20 titi de 28:4; Numeri 3:1-13.
31. Eṣe ti a ko fi sọ awọn alufa Aaroni di ọba ni Israeli?
31 Nipa bayi ẹya Judah ko ni ipin kankan ninu oye Genesisi 49:10; 1 Kronika 5:2) Nitorina, ni Israeli igbánì, oyè ọba ati oyé alufa li a yà si ọtọtọ, Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ li a ko sọ di ọba ati alufa, nipa bayi nwọn yatọ si Melkisedeki.
alufa Israeli igbánì, nitoripe lati inu ẹya yi ni Messiah ‘‘alaṣẹ’‘ na, ẹniti a npe ni ‘‘Ṣiloh’‘ yio ti wá, ẹniti ’’awọn enia yio gbọ tirẹ̀.’‘ (32. Awọn ajọ wo li a gbọdọ pamọ lọdọdun ni Israeli?
32 Gẹgẹ bi majẹmu Ofin na ti wi, ajọdun mẹta ti o jẹ ti orilẹ-ede ni gbogbo enia nilati ṣe nibi agọ ijọsin li ọdọdun. ‘‘Lẹmẹta li ọdun ni ki gbogbo awọn ọkunrin rẹ ki o farahan niwaju [Jehofah] Ọlọrun rẹ, ni ibi ti on o gbe yàn; ni Ajọ akara alaiwu, ati ni Ajọ ọsẹ, ati ni Ajọ awọn agọ, ki nwọn ki’o má si ṣe ṣánwá wá. si iwaju [Jehofah]. Ki o mu ọrẹ wá bi agbara rẹ̀ ti to, gẹgẹ bi ibukun [Jehofah] Ọlọrun rẹ ti o fi fun ọ.’‘ (Deuteronomi 16:16, 17; Eksodu 34:1, 22-24) Ajọ akara alaiwu li a nṣe nitori onjẹ alẹ Irekọja ọdọdun eyiti o ṣe iranti idande Israeli kuro ni Egipti. Ajọ ọsẹ li a nṣe ni ádọta ọjọ, eyini ni, lẹhinti ọsẹ meje ba ti kọja bẹrẹ lati Nisani 16; ao si mu awọn akọso eso ikore alikama wá si iwaju Jehofah li adọta ọjọ na (tabi, Pentikosti). Ajọ agọ li a si tun npe ni ’’ajọ ikore’‘ ni ipari ọdun. Awọn ajọ ọdọdun wọnyi ní awọn irubọ wọn ti a ṣeto rẹ̀ fun Jehofah.—Lefitiku 23:4-21, 33-43.
33. Nigbawo li a nṣe Ọjọ Iwẹnumọ, esitiṣe ti a fi nilati ma ṣe awọn irubọ rẹ̀ lati ọdun de ọdun?
33 Ọjọ marun ki ajọyọ ajọ agọ to bẹrẹ, ‘‘ọjọ iwẹnumọ ẹṣẹ’‘ ọdọdun (Yom Kippur) li a nilati ṣe, li ọjọ kẹwa oṣu keje oṣu oṣupa bi a ti ṣe kà a lati oṣu iruwe Nisani tabi Abibu. Eyini yio jẹ ni Tishri 10. Li ọjọ yi iwẹnumọ kan li ao ṣe fun gbogbo ẹṣẹ orilẹ-ede ninu ibatan majẹmu pẹlu Jehofah, eyiyi si jẹ ọjọ kan ninu ọdun nigbati Aaroni olori alufa yio wọ ibi Mimọ Julọ ninu agọ ajọ ti yio si wọ́n ẹjẹ awọn ẹran iwẹnumọ ẹṣẹ (akọ malu kan ati ewurẹ kan) siwaju apoti ẹri mimọ ti majẹmu na, eyiti o ní ninu Ofin Jehofah ti a kọ silẹ. (Lefitiku 23:26-32; 16:2-34) Amọ ṣa o, iku ati ẹjẹ awọn ẹran ti ki iṣe awọn enia wọnyi ko le mu ẹṣẹ awọn enia kuro nitotọ awọn ẹniti a fi awọn ẹranko na si abẹ rẹ̀. O jẹ nitori idi na gan pe iku ati ẹjẹ awọn ẹran irubọ wọnni ko mu ẹjẹ awọn enia kuro nitotọ li o mu ki a má ṣe irubọ Ọjọ Iwẹnumọ ẹṣẹ lati ọdun de ọdun.
34. Kini majẹmu Ofin fihan pe Ọlọrun mbere fun mimu ẹṣẹ enia kuro, esitiṣe ti ko fi si ọmọ Israeli kan ti o le pese ohun ti a mbere?
34 Awa le ri idi fun eyi. Ninu majẹmu Ofin, Ọlọrun paṣẹ ni kedere pe: ‘‘Bi ibi kan ba si pẹlu, njẹ ki iwọ ki o fi ẹmi dipo ẹmi. Fi oju dipo oju, ehín dipò ehín, ọwọ dipo ọwọ, ẹsẹ dipo ẹsẹ. Fi ijona dipo ijona, ọgbẹ́ dipo Ọgbẹ̀, ìnà dipo ìnà.’‘ (Eksodu 21:23-25; Deuteronomi 19:21) Li ede miran, pẹki nilati ko pẹki, ohun kan ti o ni iye kanna nilati wa fun ohun kanna ti iye wọn dọgba, Nitorina iwaláyé enia kan ti a ko dẹbi fun nilati lọ fun iye enia kan ti o bọ si abẹ idalẹbi. Idi ni eyi ti a fi kọ ọ sinu Orin Dafidi 49:6-10 pe: ‘‘Awọn ti o gbẹkẹle ọrọ̀ wọn, ti nwọn si nṣe ileri li ọpọlọpọ ọrọ̀ wọn; ko si ẹnikan, bi o ti wu ki o ṣe, ti o le ra arakunrin rẹ̀, bẹni ko le san owo irapada fun Ọlọrun nitori rẹ̀; (Nitori irapada ọkàn wọn iyebiye ni, o si dẹkun lailai); Niti pe o fi mọ wà lailai, ki o má ṣe ri isa-oku. Nitori o nri i pe awọn ọlọgbọn nkú.’‘ Irapada kan ti o ṣe rẹgi nilati wa, ko si si ọkan ninu awọn ọmọ Israeli ti o kun fun ẹṣẹ ti o le pese eyini lati rà iye pipe pada eyiti Adamu ti sọnu.
35. Kini ti ṣẹlẹ si oye alufa Aaroni, nitorina nibo li o yẹ ki a yiju si fun ẹbọ irapada idande?
35 Oyè alufa Aaroni ti o nṣe irubọ awọn ẹran lasan ni ile mimọ Ọlọrun rekọja lọ ni ọgọrun ọdun mọkandilogun sẹhin, ni ọdun 70 C.E. nigbati a pa Jerusalemu ati tempili rẹ̀ run lati ọwọ awọn ọmọ ogun Romu. Ko si ohun miran lati ṣe bikoṣe lati yiju si Messiah Ọba ẹniti Jehofah Ọlọrun bura fun lati sọ ọ di ‘‘alufa titilai nipa ẹsẹ Melkisedeki.’‘ (Orin Dafidi 110:1-4) Ẹni yi nilati jẹ ‘‘iru-ọmọ obirin Ọlọrun’‘ li ọrun, iru-ọmọ na ti Ọlọrun yan ti o si ranlọwọ lati fọ́ ori ẹni buburu na ti ‘‘ejo’‘ ni Edeni ṣapẹrẹ. Bi ẹni yi ko ba nilati pese ẹbọ irapada fun gbogbo araiye, nigbana ko si iranlọwọ kankan fun awa enia, ko si ifojusọna fun iye aiyeraiye ninu eto titun labẹ Jehofah Ọlọrun. Nitorina, nigbana, awọn ẹran irubọ ti a npa ni ‘‘ọjọ iwẹnumọ ẹṣẹ’‘ Israeli titi di ọgọrun ọdun ekini C.E. nilati jẹ apẹrẹ; nwọn nilati ṣapẹrẹ lọna asọtẹlẹ ẹbọ irapada ti a nfẹ eyiti Messiah nilati pese ẹniti o di alufa Melkisedeki, olu-fọ́ ori ejo na.
36. Bẹ gẹgẹ, bawo li a ti gbọdọ wo awọn ajọdun wọnni ti a nṣe labẹ majẹmu Ofin?
36 Bẹ gẹgẹ pẹlu awọn ajọdun ọdọdun wọnni eyiti majẹmu Ọlọrun gbeka ori Israeli igbánì. Nwọn ki iṣe awọn akoko igbadun ati itura fun orilẹ-ede ti ko ni itumọ kan lasan. Nwọn ní ijẹpataki alasọtẹlẹ. Ni jijẹ awọn akoko alayọ, nwọn ṣapẹrẹ awọn ipese alayọ ọjọ ọla ti Ọlọrun ti ṣe fun araiye. Itumọ wọn onibukun ni Ọlọrun sọ di mimọ̀ li akoko rẹ̀ ni ibamu pẹlu ’’ete aiyeraiye’‘ rẹ̀.
ORILẸ-EDE KAN PẸLU AWỌN ANFANI YIYANILẸNU
37. Anfani wo ni majẹmu Ofin fifun awọn ọmọ Israeli?
37 Ṣugbọn, ọmọ Israeli kankan ha le jere iye aiyeraiye fun ara rẹ̀ nipa pipa majẹmu Ofin mọ pẹlu Ọlọrun laitase, laisi riré apa ti o kerejulọ ninu rẹ̀ kọja bi? Majẹmu Ofin na fun ọmọ Israeli kọkan li anfani lati fihan pe on le ṣe bẹ. Ninu Lefitiku 18:5 a tọka si anfani yi, ninu awọn ọrọ wọnyi: ‘‘Ẹnyin o si má pa ilana mi mọ́, ati ofin mi: eyiti bi enia ba ṣe, on o má yẹ̀ ninu wọn: Emi ni [Jehofah].’‘ Nitorina, bi eyikeyi ninu ọmọ Israeli ba pa Ofin na mọ laitase ti o si jere iye aiyeraiye nipa iṣẹ ọwọ on funrarẹ̀, on ko wá anfani ẹbọ irapada majẹmu Ofin na. Bẹni ko si ni wá ibukun Ileri Abrahamu. Genesisi 12:3; 22:18) Iru olupa Ofin mọ ni pipe bẹ yio gbe ododo ara rẹ̀ kalẹ ati itoye iwaláyè.
38, 39. (a) Kini fihan boya eyikeyi ninu awọn ọmọ Israeli jere iye nipa pipa Ofin mọ perepere? (b) Nitorina iṣẹ alufa tani niwaju Ọlọrun li a nwá?
38 Ṣugbọn, ani woli Mose pápá kú. Ani Aaroni olori alufa pápá ku. Ani gbogbo ọmọ Israeli miran lati igba igbekalẹ majẹmu Ofin na titi di igba imukuro oye alufa Aaroni ni ọdun 70 C.E., bẹni, titi di oni oloni, li o ti ku. Ani ọgọrun ọdun lati igba iparun tempili Jerusalemu lati ọwọ awọn ọmọ ogun Romu awọn ẹniti a mọ bi ọmọ Israeli ode oni nṣe ajọyọ iru Ọjọ Iwẹnumọ kan tabi Yom Kippur loni. Eyiyi ninu ara rẹ̀ jẹ ifaramọ kan pe nwọn nfẹ wiwẹmọ kuro
ninu ẹṣẹ, bẹni, ikuna wọn lati pa Ofin mọ ni pipe perepere ki nwọn si jere iye aiyeraiye nipa awọn iṣẹ ọwọ wọn. Bi wọn ko ba si le ṣe eyi labẹ majẹmu Ofin na, bawo li ẹnikẹni ti o kù ninu wa ti a jẹ enia alaipe ṣe le ṣe bẹ?39 Loju ohun ti majẹmu Ofin mu ki o ṣe kedere gbangba-gbàngbà, gbogbo wa li a di ẹlẹbi niwaju Ọlọrun ẹniti iṣẹ rẹ̀ jẹ pipe. (Deuteronomi 32:4) Gẹgẹ bi woli Isaiah ti wi ni eyiti o ju ẹdẹgbẹrin ọdun sẹhin lẹhinti a ti da majẹmu Ofin na pẹlu Israeli: ‘‘Gbogbo ododo wa dabi àkísà ẹlẹgbin.’‘ (Isaiah 64:5, JPS) Gbogbo wa li o nfẹ iranlọwọ Alufa Melkisedeki ti a ṣeleri na, ẹniti yio jẹ alufa titi lai.
40. Kini Mose ṣe ni Nisani 1, 1512 B.C.E., niti ijọsin Ọlọrun, kini si ṣẹlẹ lẹhinna?
40 Yipada nisisiyi si ọdun idasilẹ majẹmu na larin Jehofah Ọlọrun ati Israeli nipasẹ Mose alarina na. Ọdun oṣupa na pari, Nisani 1 kalenda ọdun 1512 B.C.E. si wọle de. Li ọjọ na Mose pa aṣẹ Ọlọrun mọ o ‘‘si kọ agọ ajọ’‘ fun ijọsin Ọlọrun ti yio bẹrẹ. Liẹhinna ni Mose fi aṣọ wọ Aaroni ẹgbọn rẹ̀ ati awọn ọmọ Aaroni pẹlu awọn aṣọ oyé wọn o si fi ami ororo yan wọn lati ṣiṣẹ gẹgẹ olori alufa ati awọn alufa ọmọ-abẹ. ‘‘Bẹni Mose pari iṣẹ na. Nigbana li awọsanma bo Agọ ajọ, ogo [Jehofah] si kún inu Agọ na. Mose ko si le wọ inu Agọ ajọ lọ, nitoriti awọsanwa wà lori rẹ̀, ogo [Jehofah] si kún inu agọ na.’‘—Eksodu 40:1-35
41. Ẹri wo ni ifihan na jẹ, nigbawo li a si pari ifijoye alufa na?
41 Ẹri ti a le fojuri wa pe Jehofah ti tẹwọgba ile ijọsin yi ati pe o ti ya a si mimọ fun ete Rẹ̀. Li ọjọ keje oṣu ekini na Nisani (tabi, Abibu) a ṣe aṣepari ifijoye ati fifun li agbara oye alufa Aaroni, lẹhinna nwọn le ṣe abojuto gbogbo ohun ti o jẹmọ ijọsin atọrunwa pẹlu aṣẹ nibi mimọ na.—Lefitiku 8:1 titi de 9:24
42. Yatọ si jijẹ Ọlọrun wọn fun ijọsin, lẹhinna kini Jehofah tun jẹ fun Israeli, laisi nini aṣoju kan ti a le fojuri?
42 Jehofah li Ọlọrun na ẹniti o paṣẹ fun ti o si di ọranyan fun orilẹ-ede na Israeli lati sin. Ki iṣe Ọlọrun nikan li on jẹ fun wọn. O tun jẹ Alakoso wọn olotọ, Ọba wọn, ẹniti nwọn jẹ ni gbese itẹriba ati iṣotitọ. Deuteronomi 33:5 woli Mose tọka si orilẹ-ede Israeli gẹgẹ bi Jeṣuruni tabi ‘‘Aduroṣinṣin’‘ nitori wiwọ ti o wọ̀ inu majẹmu Ofin o si wipe: ‘‘O si jẹ ọba ni Jeṣuruni, nigbati olori awọn enia, awọn ẹya Israeli pejọ pọ.’‘ (Translation by The Jewish Publication Society of America) Ọrọ olotu ni isalẹ iwe lori ẹsẹ na lati ọwọ ologbe Dr. J. H. Hertz, C. H. wipe: ‘‘Nipa bayi Ijọba Ọlọrun bẹrẹ lori Israeli.’‘ (Pentateuch and Haftorahs, Soncino Press, oju iwe 910) Jehofah li Ọba wọn ọrun ti a ko le fojuri. On ko wá enia ọba ori ilẹ aiye kan ṣe e fojuri lati ṣoju fun U ni Israeli.—Genesisi 36:31.
Aigbọran si awọn ofin ati aṣẹ Rẹ̀ yio jẹ orikunkun ati aiṣétọ nitorina. Ni titẹnumọ otitọ na, ninu43, 44. Bawo li a ti ṣe ojurere si Israeli igbánì lọna ojulowo to ni ifiwera pẹlu awọn orilẹ-ede miran, bawo nitorina ni nwọn ṣe le yin Jehofah?
43 Wo bi orilẹ-ede yi ti jẹ olorire giga to ti o jẹ apapọ awọn atọmọdọmọ Abrahamu, Isaaki ati Jakobu (Israeli) ti a si ti mu wọn wa sinu majẹmu kan pẹlu Ọlọrun otitọ ati alaye! Nwọn ni ijọsin totọ rẹ̀ nwọn si ngbadun ireti didi ‘‘ijọba alufa ati orilẹ-ede mimọ’‘ fun U.
44 Woli Amosi wipe: ‘‘Ẹ gbọ ọrọ yi ti [Jehofah] ti sọ si nyin, ẹnyin ọmọ Israeli, si gbogbo idile ti mo mu goke lati ilẹ Egipti wa, wipe, Ẹnyin nikan ni mo mọ ninu gbogbo idile aiye.’‘ (Amosi 3:1, 2) O jẹ ifiwera ti o ṣe dede ti onipsalmu sọ ninu ọkan ninu psalmu Haleluyah na, wipe: ‘‘O fi ọrọ rẹ̀ han fun Jakobu, aṣẹ rẹ̀ ati idajọ rẹ̀ fun Israeli. Ko ba orilẹ-ede kan ṣe bẹ ri; Bi o si ṣe ti idajọ rẹ̀ ni, nwọn kò mọ wọn. Ẹ; fi iyin fun [Jehofah].’‘ (Orin Dafidi 147:19, 20) Dajudaju orilẹ-ede na ti a ṣe ojurere si ní idi rere lati yin Jehofah nipa pipa majẹmu rẹ̀ mọ. Boya nwọn ṣe bẹ li a nilati fihan nisisiyi nigba akoko ohun ti a le pe ni Sanmani Majẹmu Ofin eyiti o ti bẹrẹ nisisiyi.
[Ibeere]