Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Titọpasẹ Ila Idile “Iru-ọmọ” na Gẹgẹbi Enia

Titọpasẹ Ila Idile “Iru-ọmọ” na Gẹgẹbi Enia

Ori 7

Titọpasẹ Ila Idile ‘‘Iru-ọmọ’‘ na Gẹgẹbi Enia

1.Eṣe ti awọn ọran Abeli, Enoku Noa mu ki Satani Eṣu tun gbékuta ju ninu ipetepero rẹ̀ lati ba ‘’iru-ọmọ’’ na jẹ?

OHUN ti o wà ninu ọkàn ‘‘ete aiyeraiye’‘ Ọlọrun ni ‘‘iru-ọmọ’‘ na ti ‘‘obirin’‘ Ọlọrun yio bí. Ijakadi na ti o bẹrẹ ninu ọgba Edeni lárin Satani ati Ọlọrun simi lori ‘‘iru-ọmọ’‘ agbayanu yi. Eyiyi nilati ri bẹ̀, nitoripe ‘‘iru-ọmọ’‘ na li a nilati mu jade laipẹ lati fọ ori Ejo Nla na, Satani Eṣu si mọ̀ pe on li o ni ‘‘ori’‘ na ti a ní lọkan. (Genesisi 3:15) Satani ti pinnu lati ba iduroṣinṣin ‘‘iru-ọmọ’‘ ti mbọ na jẹ ki o si tipa bayi sọ ọ di alaiyẹ fun ete Ọlọrun. Nigba Ikun-omi apa ekini ninu ijakadi na lárin Ọlọrun ati Satani dopin, ṣugbọn pẹlu ipenija kan lodi si Satani. On ti kuna lati ba iduroṣinṣin o kere tan awọn ọkunrin mẹta jẹ ti nwọn jẹ atọmọdọmọ ọkunrin ati obirin ekini, iduroṣinṣin awọn ẹniti on ti petepero lati bajẹ. Abeli, Enoku ati Noa ti sọ ipo igbẹkẹle Satani di ahẹrẹpẹ nwọn si ti mu ki o gbekuta si i ninu ilepa rẹ̀ lati ba ‘‘iru-ọmọ’‘ na jẹ.

2Ọtalelẹgbẹta o din meji ọdun ti o tẹle e lẹhinti Ikun-omi na pari nilati fi iṣipaya han gán nipa kulẹkulẹ nipa ‘‘iru-ọmọ! ’’ obirin Ọlọrun na. Lẹhin ikun-omi na gbogbo araiye titi di oni oloni le tọpasẹ ila idile rẹ̀ lati ọdọ Noa ẹniti o kàn ọkọ arki na ti o la ikun-omi na ja. Nitorina nisisiyi aiye araiye li a fun ni ibẹrẹ ododo, nitoripe ‘’Noa ba Ọlọrun otitọ rin’’. (Genesisi 6:9) Alaipe li on jẹ nipa ajogunba, ṣugbọn, niti iwarere, on jẹ alailabuku, alailẹgan, niwaju Ọlọrun. Bawo li a ti kún fun ọpẹ to, fun eyini, awa ti a jẹ atọmọdọmọ rẹ̀! Kete ti o jade kuro ninu arki na ti o si fi ẹsẹ tẹ̀ Oke Ararati, Noa ṣáju araiye ninu ijọsin Oludábòbò araiye, Jehofah Ọlọrun.

2. Araiye loni nilati dupẹ pé Noa fun wọn ni iru ibẹrẹ wo ninu igbesi aiye lẹhin ikun-omi na? Bawo si ni?

“Noa si tẹ pẹpẹ fun [Jehofah]; o si mu ninu ẹranko mimọ gbogbo, ati ninu ẹiyẹ mimọ gbogbo, o si rú ọrẹ-ẹbọ sisun lori pẹpẹ na. (Jehofah) si gbọ orùn didun na; (Jehofah) si wi li ọkàn rẹ̀: ‘Emi ki yio si tun fi ilẹ rẹ́ nitori enia mọ; nitori iro ọkàn enia ibi ni lati igba ewe rẹ̀ wá; bẹli emi ki yio si tun kọlu ohun aláye gbogbo mọ bi mo ti ṣe. Niwọn igba ti aiye yio wà, igba irugbin, ati igba ikore, igba otutu ati oru, igba ẹrun on òjò, ati ọsan ati oru, ki yio dẹkun.’”—Genesisi 8:20-22; fiwe Isaiah 54:9.

3. Bawo ni asotẹlẹ Lameki nigba bibi Noa ṣe jẹ otitọ, kini oṣumare na si wa di ami rẹ?

3 Asọtẹlẹ ti Lameki baba Noa kede lé e lori nigba ìbí rẹ̀ fihan pe o tọ. (Genesisi 5:29) Egún atọrunwa ti a kede sori ilẹ lẹhin ode ọgba Edeni lẹhin irekọja Adamu li a mu kuro, Noa (ẹniti itumọ orukọ rẹ̀ njẹ ‘‘Isimi’‘) mu ki orùn didun goke lati inu ẹbọ orùn didun rẹ̀ lọ sọdọ Ọlọrun o si ṣe okunfa pipaṣẹ ti Ọlọrun paṣẹ fun isimi fun araiye kuro ninu iṣẹ wọn niti riro ilẹ ti a ti gégun fun Ọlọrun si tun mu ki oṣumare ekini ti a rohin rẹ̀ farahan ninu imọlẹ ôrùn ti nran nisisiyi ni táràtà sori ilẹ aiye nitori mimu ti a mu ikúiku omi kuro. Ni tikọkasi oṣumare gẹgẹbi ami idaniloju kan, Jehofah ṣeleri pe ‘‘omi ki yio si di kíkún mọ lati pa gbogbo ẹda run.’‘ Ko tun ni si ikun-omi mọ.—Genesisi 9:8-15.

4. Nigbati awọn ọmọ Noa mẹta ati awọn aya wọn ti la ikun-omi ja pẹlu Noa, awọn ibere wo li o wa dide nisisiyi niti ‘’iru-ọmọ ti a ṣeleri na?

4 Awọn ọmọ Noa mẹta, Ṣemu, Hamu ati Jafeti, ati awọn aya wọn là a ja pẹlu rẹ̀ ati iyawo rẹ̀. Nisisiyi, ewo ninu awọn mẹtẹta wọnyi li o nilati jẹ ẹni na ti o ni ila idile nipasẹ eyiti ao gba tọpasẹ ifarahan ‘‘iru-ọmọ’‘ ‘’obirin’’ Ọlọrun na lori ilẹ aiye? Yiyan na ti a nilati ṣe yio ni iṣe lọtọtọ pẹlu awọn iran mẹta na ti yio jade wa lati ọdọ awọn baba-nla na, Ṣemu, Hamu ati Jafeti. Asọtẹlẹ na ti Ọlọrun misi Noa lati kede sori awọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹta li akoko lile koko kan ṣe igbekalẹ ọna eyiti ojurere ati ibukun atọrunwa na yio gba. Kini ipilẹ na fun eyi?

5. Kini mu ki Noa kede ègún sori Kenaani ọmọ Hamu?

5 Ninu igbọran si aṣẹ Ọlọrun fun awọn ọmọ Noa mẹta lati gbilẹ lori ilẹ aiye, Ṣemu di baba fun Arfaksadi li ọdun keji lẹhin kikun-omi. (Genesisi 11:10) Nigbati o ya, Hamu di baba fun Kenaani. (Genesisi 9:18; 10:6) Akoko diẹ lẹhin bibi Kenaani akoko kan wà nigbati Noa, fun idi kan ti a ko sọ, mutiyo lati inu ọgba ajara rẹ̀. Hamu wọ agọ Noa lọ o si ri i ni idubulẹ ni ihoho, laifi aṣọ bora, ṣugbọn ko ṣe nkankan lati fi ihoho baba rẹ̀ pamọ. Kakabẹ, o sọ ọ fun Ṣemu ati Jafeti. Pẹlu Ọwọ ti o yẹ fun baba wọn, Ṣemu ati Jafeti kọ̀ lati ri ihoho baba wọn, pẹlu fifi ẹhin rin lọ ṣọdọ baba wọn, nwọn nà aṣọ kan le e lori. Nwọn ko lo anfani ihoho baba wọn, nwọn fihan nwọn si pa ọ̀wọ̀ giga fun baba wọn mọ ati gẹgẹbi woli Jehofah.

“Noa si ji kuro li oju ọti-waini rẹ̀, o si mọ ohun ti ọmọ rẹ̀ kekere ṣe si i. O si wipe: ‘Egbé ni fun Kenaani. Iranṣẹ awọn iranṣẹ ni yio mii ṣe fun awọn arakunrin rẹ̀’ O si wipe: ‘Olubukun ni (Jehofah) Ọlọrun Ṣemu; Kenaani yio má ṣe iranṣẹ rẹ̀. Ọlọrun yio mu Jafeti gbilẹ, yio ma gbe agọ Ṣemu. Kenaani yio si ma ṣe iranṣẹ wọn.’”—Genesisi 9:20-27.

6. Gẹgẹbi aṣọtẹlẹ Noa ti wi, nipasẹ ọmọ wo ni ila idile messiah yio gba?

6 Noa ko mutiyo nigbati o kede awọn ọrọ wọnni. On ko gegun fun gbogbo iran ti o jade wa lati inu Hamu, nitori ikuna Hamu lati fi ọ̀wọ̀ han, ni pataki fun woli Ọlọrun. Nitorina Ọlọrun misi Noa lati gegun fun ọmọ Hamu kanṣoṣo, eyini ni, Kenaani, ẹniti awọn atọmọdọmọ rẹ̀ ngbe ni ilẹ Kenaani ni Palestine. Nitôtọ awọn ọmọ Kenaani di iranṣẹ fun awọn atọmọdọmọ Ṣemu, nigbati Ọlọrun mu awọn ọmọ Israeli wá si ilẹ Kenaani ni iṣedede pẹlu ileri Rẹ̀ fun Abrahamu Heberu na. Ṣemu gbe li aiye fun ẹdẹgbẹta o le meji ọdun lẹhin ibẹrẹ Ikun-omi na, nitorina ọdun ti o lo li aiye wọ inu ti Abrahamu pẹlu adọjọ ọdun. (Genesisi11:10, 11) Noa kede Jehofah pe o jẹ Ọlọrun Ṣemu. Jehofah li a nilati bukun fun, nitoripe ibẹru Rẹ̀ li o sún Ṣemu lati fi ọ̀wọ̀ ti o yẹ han fun Noa gẹgẹ bi woli Ọlọrun. Jafeti li a nilati balo gẹgẹ bi alejo kan ninu agọ Ṣemu, ki si iṣe bi iranṣẹ bi ti Kenaani. Nipa bayi, nipa jijẹ alejo kan fun Jafeti arakunrin rẹ̀, Ṣemu li a kà si ẹniti o gaju ninu ọrọ asọtẹlẹ na. Ni ibamu pẹlu eyi, ila idile Ṣemu li o nilati dari si Messiah na.

TITẸ BABILONI DÔ

7. Ọmọ-ọmọ Hamu wo li o tẹ Ilẹ̀-ọba Babiloni dó, bawo si ni?

7 Atọmọdọmọ Hamu kan ti ko ṣe rere ni Nimrodu ọmọ-ọmọ rẹ̀. Ni lila a ja fun adọta-le-ni-ọdunrun ọdun lẹhin ibẹrẹ ikun-omi na, Noa waláyè lati ri idide ati laisi aniani iṣubu ọmọ-ọmọ rẹ̀ yi. (Genesisi 9:28, 29) Nimrodu gbe eto kan kalẹ eyiti o ṣiṣẹ gẹgẹbi apakan ‘‘iru-ọmọ’‘ ti a le fojuri fun Ejo Nla na, Satani Eṣu. Genesisi 10:8-12 wipe: ‘‘Kuṣi si bí Nimrodu: on si bẹrẹ si idi alagbara li aiye. On si ṣe ogboju ọdẹ niwaju (‘‘ni idojúja kọ,’‘NW) (Jehofah): nitori na li a ṣe nwipe, Gẹgẹ bi Nimrodu ogboju ọdẹ niwaju (‘’ni idojúja kọ,’‘ NW) (Jehofah). Ipilẹṣẹ ijọba rẹ̀ ni Babeli, ati Ereki, ati Akkadi, ati Kalne, ni ilẹ Ṣinari. Lati ilẹ na ni Aṣṣuri ti jade lọ, o si tẹ̀ Ninefe, ati ilu Rehoboti, ati Kala dó. Ati Reseni agbedemeji Ninefe on Kala: eyi na ni ilu nla. Gẹgẹ bi eyi ti wi, Nimrodu gbe Ilẹ-ọba Babiloni akọkọ kalẹ.

8, 9. (a) Ẹṣe ti Jehofah ko fi yan Babeli gẹgẹ bi ilu na eyiti on yio fi orukọ rẹ si? (b) Ede tani a ko yipada ni Babeli?

8 Ni Babeli (awọn Griki ti nsọ ede Ju npè e ni Babiloni) ni idarudapọ ede araiye ti ṣẹlẹ, nigbati Jehofah Ọlọrun fi ilodisi rẹ̀ han nigbati nwọn nkọ ilu nla na ati ile iṣẹ isin eke kan nibẹ, nitoripe awọn ti nkọ ọ pete lati ṣe orukọ olokiki kan fun ara wọn ati lati lodisi tituka ‘’kiri si ori ilẹ gbogbo’’. Nwọn ko ri ibajẹ awọn ilu nla ti o nṣẹlẹ loni tẹlẹ. (Genesisi 11 :1-9) Biotilẹjẹpe on ni ilẹ-ọba akọkọ lori ilẹ aiye, Ilẹ-ọba Babiloni ti Nimrodu yi ki iṣe Agbara Aiye Ekini ninu akọsilẹ Bibeli. Egipti igbánì ni. Agbara iṣelu Babeli li a sọ di ahẹrẹpẹ, nitoripe awọn ti nkọ́ ọ, nisisiyi ti ntako ara wọn nitori awọn ede ti o yatọ si ara wọn, ni Jehofah tipa bayi mu ki o tuka kiri ilẹ gbogbo.

9 Jehofah Ọlọrun ko yan Babiloni gẹgẹ bi ilu na lori eyiti on yio fi orukọ rẹ̀ si. Noa ati Ṣemu ọmọ rẹ̀ ti a bukun ko ni ipa kankan ninu kikọ Babeli ati ile iṣọ isin eke rẹ̀, a ko si dà ede wọn rú.

10, 11. (a) Ni ọjọ Ṣemu ila idile wo fun ‘’iru-ọmọ ti a ṣeleri li a sọ di toro si ewo ninu awọn atọmọdọmọ rẹ? (b) Eyiyi li a fihan nipasẹ iṣipaya wo, si tani?

10 Ọdun meji lẹhin iku Noa ni 2020 B.C.E., a bi Abrahamu ninu ila idile Ṣemu, ẹniti o sì mbe láyé. Atọmọdọmọ yi fihan pe on jẹ olusin Jehofah, Ọlọrun Ṣemu. Ṣemu ti le ni itẹlọrun nlanla nigbati o gbọ nipa ifihan pe Jehofah rọ̀ mọ́ “ete aiyeraiye” rẹ̀ eyiti On ti gbekalẹ ni ọgba Edeni lẹhin irekọja Efa ati Adamu. O sọ wiwá “iru-ọmọ” “obirin” Ọlọrun na di tõro si ila idile Abrahamu, lati inu gbogbo awọn atọmọdọmọ Ṣemu. Ṣugbọn kini ifihan atọrunwa na fun Abrahamu, ẹniti a npe ni Abramu nigbana?

11 Abramu (Abrahamu) wà ni Mesopotamia, ni ilu nla Uri ti awọn ara Kaldea ti ko jinna si Babiloni (Babeli), nigbati a fun u ni ifihan na. Genesisi 12:1-3 sọ fun wa: ‘‘ (Jehofah) si ti wi fun Abramu pe, Jade kuro ni ilẹ rẹ, ati kuro lọdọ awọn ara rẹ, ati kuro ni ile baba rẹ, si ilẹ kan ti emi o fi hàn ọ. Emi o si sọ ọ di orilẹ-ede nla, emi o si busi i fun ọ, emi o si sọ orukọ rẹ di nla; ibukun ni ìwọ o si jasi. Emi o bukun fun awọn ti nsure fun ọ, ẹniti o nfi ọ ré li emi o si fi ré; ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye.’’

12. Fun tani ni iṣipaya na jẹ ‘‘ihinrere,’’ sanmani wo li a le sọ pe o ti bẹrẹ nigba iṣipaya na?

12 Gbogbo idile aiye’‘—eyini kàn awọn idile wa loni ninu ọgọrun ọdun lọna ogún yi! Awọn wọnni ti o jẹ ti idile wa le ri ibukun gba nipasẹ Abramu (Abrahamu) igbánì yi! Ihinrere li eyini jẹ, nitôtọ! O si ṣẹlẹ sori aiye araiye lẹhin Ikun-omi nigbana lọhun ni ọgọrun ọdun lọna ogun ṣaju Sanmani Igba tiwa. Ohun ti eyi tumọsi li a ṣalaye rẹ̀ lẹhinna ninu awọn ọrọ onimisi wọnyi: ‘‘Nitorina ki ẹnyin ki o mọ̀ pe awọn ti iṣe ti igbagbọ, awọn na ni iṣe ọmọ Abrahamu. Bi iwe mimọ si ti ri i tẹlẹ pe, Ọlọrun yio da awọn Keferi lare nipa igbagbọ, o ti wasu ihinrere ṣaju fun Abrahamu, o nwipe, Ninu rẹ li a o bukun fun gbogbo orilẹ-ede.’‘(Galatia 3:7, 8) Nipa eyini a le wi pẹlu ẹtọ pe Sanmani Ihinrere (Aiye Ihinrere, gẹgẹ bi awọn kan le ti fẹ pè e) bẹrẹ nibẹ lọhun kete ṣaju ki Abrahamu to ṣe igbọran si aṣẹ atọrunwa.

13. (a) Kini ipo ara Abrahamu ti ri nigbati aṣẹ Ọlọrun de si i, nitorina kini ohun ti o ṣe pataki ju pẹlu Ọlọrun? (b) Nigbawo ni Abrahamu rekọja Odo Euferate?

13 Otitọ kan ti a nilati kiyesi nihin, pẹlu, ni pe, li akoko ti Ọlọrun yàn a lati jẹ ọna fun bibukun gbogbo idile aiye, a koiti kọ Abrahamu ni ila nipa ti ara. Aṣẹ Ọlọrun fun u lati kọ ara rẹ̀ ni ila ati gbogbo ọkunrin ti mbẹ ninu idile rẹ̀ ko dé titi bikoṣe o kere tan ni ọdun mẹrinlelogun lẹhinna, ọdun na ti o ṣaju bibi Isaaki ọmọ rẹ̀ (1918 B.C.E.). Bi ki iba ṣe ipo ti Abrahamu wà nipa ti ara, kini, nigbana, ni ohun ti Ọlọrun kasi? On ni igbagbọ Abrahamu. Jehofah Ọlọrun mọ pe Abrahamu gba On gbọ. Ki iṣe lasan ni On pa aṣẹ na fun Abrahamu lati fi ilẹ rẹ̀ silẹ. Kiakia ni Abrahamu lọ o si ko idile rẹ̀ lọ si Harani ni ariwa si iwọ orùn, ati lati ibẹ, lẹhin Tera baba rẹ̀ ni Harani, o rekọja Odo Euferate o si lọ si ilẹ na ti Ọlọrun ntẹsiwaju lati fihan Rirekọja ti o rekọja Odo Euferate ṣẹlẹ ni Nisani 14 nigba iruwe ọdun 1943 B.C.E., tabi 430 ọdun ṣáju ṣiṣe ajọdun Irekọja ekini lati ọwọ awọn atọmọdọmọ Abrahamu ni Egipti.—Eksodu. 12:40-49; Galatia 3:17.

14. Kini Jehofah sọ fun Abraham. ni ilẹ Kenaani, lẹhinna kini Abrahamu si ṣe?

14 Woli Mose ṣe akọsilẹ eyi, ni kikọwe pe: ’‘‘Bẹli Abramu lọ, bi (Jehofah) ti sọ fun u; Lọti si ba a lọ. Abramu si jẹ ẹni arundilọgọrin ọdun nigbati o jade ni Harani. Abramu si mu Sarai aya rẹ̀, ati Loti ọmọ arakunrin rẹ̀, ati gbogbo ini wọn ti nwọn kojọ, enia gbogbo ti nwọn ni ni Harani, nwọn si jade lati lọ si ilẹ Kenaani; ni ilẹ Kenaani ni nwọn si wá si. Abramu si la ilẹ na kọja lọ si ibi ti a npe ni Ṣekemu, si igbo More. Awọn ara Kenaani si wà ni ilẹ na ni igba na. (Jehofah) si fi ara han fun Abramu, o si wipe, Iru- ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun: nibẹ li o si tẹ pẹpẹ fun (Jehofah) ti o fi ara han a.’‘—Genesisi 12:4-7; Iṣe 7:4.

15. Eṣe ti ileri Ọlọrun fun Abrahamu nipa ‘‘iru-ọmọ’‘ kan nilati fi bere iṣẹ iyanu, eyiyi si kàn iṣẹ iyanu titobiju wo sibẹ?

15 Nipa. bayi, biotilẹjẹpe ni akoko na Abramu, ni ọjọ ori marundinlọgọrin ọdun, koiti ni awọn ọmọ kankan, aya rẹ̀ Sarai ọlọdun marundinladọrin koiti bimọ kankan, sibẹ Jehofah ṣeleri pe Abramu yio ni iru-ọmọ tabi ọmọ kan, ẹniti Jehofah yio fi ilẹ Kenaani fun. Abrahamu tẹwọgba ileri atọrunwa na. pẹlu igbagbọ. Nitoripe, gẹgẹbi agbara ibimọ obirin ti ri li akoko na nigbana, eyiyi sunmọ ṣiṣe ileri iṣẹ iyanu Ọlọrun. Ọdun mẹrinlelogun lẹhinna, nigbati Abrahamu gbọ pe on nilati ni ọmọ kan lati ọdọ aya rẹ̀ Sara o rẹrin o si wi ninu ọkan rẹ̀ pe: ‘‘A o ha bimọ fun ẹni ọgọrun ọdun? Sara ti iṣe ẹni adọrun ọdun yio ha bimọ bi?’‘ (Genesisi 17:17; 18:12-14) Bi eyini ba jẹ ‘‘aramanda’‘ sibẹ, ohun ti o tun jẹ iyalẹnu ju yio jẹ iṣẹ iyanu na ti yio mu asọtẹlẹ Ọlọrun ṣẹ ninu Genesisi 3:15. Eyiyi jẹ nitoripe ‘‘obirin’’ Ọlọrun jẹ ti ọrun, ‘‘iru-ọmọ’‘ rẹ̀ ti a si ṣeleri yio jẹ ti ọrun sibẹ ‘‘iru-ọmọ’‘na li a o sopọ mọ ila idile Abrahamu lori ilẹ aiye. Li ọna bayi ‘’iru-ọmọ’’ ‘’obirin’‘ Ọlọrun yi li a le pe ni ‘‘iru-ọmọ Abrahamu,’‘ bẹni, ‘‘ọmọ Abrahamu.’‘

16. Ileri Ọlọrun lati mu orilẹ-ede ati ọba jade lati inu Abrahamu ati Sara gbe awọn ibere wo dide nipa ‘‘iru-ọmọ’‘ na?

16 Li akoko na ti Ọlọrun, nipasẹ angeli rẹ̀, fi mu u da Abrahamu loju pe o nilati ni ọmọ kan lati ọdọ Sara aya rẹ̀, ti a nilati pe ni Isaaki, Ọlọrun sọ fun Abrahamu pe: ‘‘Emi o si mu ọ bi si i pupọpupọ, ọpọ orilẹ-ede li emi o si mu ti ọdọ rẹ wa, ati awọn ọba ni yio ti inu rẹ jade wa. . ... Emi o si busi i fun u (Sara), emi o si bun ọ li ọmọkunrin kan pẹlu lati ọdọ rẹ̀ wá, bẹli emi o si busi i fun u, on o si ṣe iya ọpọ orilẹ-ede; awọn ọba enia ni yio ti ọdọ rẹ̀ wá.? (Genesisi 17:6, 16) Nitorina, nisisiyi, ewo ninu awọn ‘‘orilẹ-ede’‘ wọnni ni yio jẹ orilẹ-ede ti Jehofah ṣe oju rere si? On yio ha ni ọba kan lori rẹ̀? ‘‘Iru-ọmọ’‘ ’’obirin? Ọlọrun yio ha di ọba na bi? O jẹ iwa ẹda lati bere iru awọn ibere bawọnnì.

MELKISEDEKI

17. Ewo ni ibalo titayọ julọ pẹlu awọn ọba ni ilẹ Kenaani ti o ṣẹlẹ ninu igbesi aiye Abrahamu, esitiṣe ti Abrahamu fi san idamẹwa fun u?

17 Ṣaju eyi, Abrahamu ti ni ibalo pẹlu awọn ọba ilẹ aiye. Eyiti o ṣe pataki julọ ninu awọn ibalo bẹ ni ti akoko igbati o pade ọba ti o tayọ julọ ni ilẹ Kenaani. Abrahamu ṣẹṣẹ pari iṣẹ aigbọdọmaṣe ti gbigba ọmọ arakunrin rẹ̀ Loti la lọwọ awọn ọba mẹrin ti o kọlu ilẹ Kenaani ti o si ṣẹgun marun ninu awọn ọba wọnni ti o si ko ikogun, titi kan Loti. Ninu ipadabọ rẹ̀ lati ibi iṣẹgun awọn ọba mẹrin wọnni, Abrahamu sunmọ ilu Salemu, ni awọn oke ti o wà ni iwọ orùn Okun Oku. ‘‘Melkisedeki ọba Salemu si mu onjẹ ati ọti waini jade wa: on a si ma ṣe alufa Ọlọrun Ọga-ogo. O si sure fun u, o si wipe, Ibukun ni fun Abrahamu, ti Ọlọrun ọga-ogo, ẹniti o ni ọrun on aiye. Olubukun si li Ọlọrun ọga-ogo ti o fi awọn ọta rẹ lé ọ lọwọ. On si dá idamẹwa ohun gbogbo fun u.’‘ Niwọnbi, gẹgẹbi Melkisedeki ti sọ fun Abrahamu, Ọlọrun ọga-ogo ti fi awọn ọta Abrahamu le e li ọwọ, o wulẹ jẹ ohun ti o ba a mu rẹgirẹgi pe Abrahamu nilati fi idamẹwa ikogun na fun Melkiṣedeki alufa Ọlọrun Ọga-ogo.

18. Eṣe ti ibukun Melkisedeki lori Abrahamu ki iṣe ọrọ isọjade lasan, bawo ni Dafidi si ṣe fihan pe ẹni na ṣe pataki ninu ete Ọlọrun?

18 Ibukun Melkisedeki lori Abrahamu ki iṣe ọrọ asọjade lasan. O ṣe pataki fun ohun kan, o si wà ni iṣedede pẹlu ileri Jehofah funrarẹ̀ pe Abrahamu nilati jẹ ibukun kan fun gbogbo idile aiye—gbogbo idile nilati ri ibukun gba nipasẹ rẹ̀. (Genesisi 12:3) Melkisedeki Ọba Alufa yiyanilẹnu yi, biotilẹjẹpe afiyesi kekere li a fifun u ninu itan, ko nù mọni-loju. Ẹdẹgbẹrun ọdun lẹhinna, Ọlọrun Ọga Ogo misi ọba Salemu miran, Ọba Dafidi ti Jerusalemu, lati sọtẹlẹ ki o si fihan ni kukuru bawo ni Melkisedeki ti ṣe pataki to ninu ete Ọlọrun Ọga Ogo. Gẹgẹbi eyi ti ri, Melkisedeki jẹ apẹrẹ na fun ọba kan ti o tobiju, ọkan ti o tilẹ tobi ju Dafidi, ọkan ti yio di aigbọdọmaṣe fun Dafidi lati pe ni ’’Oluwa mi’’ Ọba iṣapẹrẹ yi ko le jẹ ẹlomiran kankan bikoṣe Messiah na, “iru-ọmọ” “obirin” Ọlọrun. Nitorina, labẹ agbara ẹmi mimọ Ọlọrun, Dafidi kọwe, ninu Orin Dafidi 110:1-4 pe:

“(Jehofah) wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ ọtun mi, titi emi o fi sọ awọn ọta rẹ di apoti-itisẹ rẹ. (Jehofah) yio nà ọpa agbara rẹ̀ lati Sioni wá: iwọ jọba lárin awọn ọta rẹ. Awọn enia rẹ yio jẹ ọrẹ atinuwa li ọjọ agbara rẹ; ninu ẹwà iwa mimọ, lati inu owurọ wa, iwọ ni ìrì ewe rẹ. (Jehofah) ti bura, ki yio si yi ọkan pada pe, Iwọ li alufa titi lai nipasẹ ti Melkisedeki.”

19. Ẹni na ti a sọtẹlẹ lati lo ọpa agbara lori Oke Sioni nilati jẹ idile tani, esitiṣe ti Dafidi ko sọ asọtẹlẹ nipa awọn ọba lati Solomoni titi de Sedekiah?

19 Sakiyesi ohun ti awọn ọrọ onimisi wọnni tumọsi. Otitọ na pe Ọba Dafidi wipe Jehofah yio ran ọpa agbara Ọba jade lati Sioni fihan pe Ọba na yio jẹ enia ti o wà lati ila idile Dafidi. Gẹgẹbi majẹmu Jehofah pẹlu Dafidi fun ijọba titi lai kan, ko si ẹnikan ti yio joko gẹgẹ bi ọba lori Oke Sioni ki o si lo agbara ọpa ọba bikoṣe enia atọmọdọmọ Dafidi. (2 Samueli 7:8-16) Nipa bayi, ẹni yi ẹniti a o rán ọpa agbara rẹ̀ jade lati Sioni li ao má pe ni ‘‘ọmọ Dafidi.’‘ Ṣugbọn ninu ọran yi Dafidi ko tọka lọna isọtẹlẹ si ọmọ rẹ̀, Ọba Solomoni, ẹniti o jẹ ọba ologo julọ ninu ila idile Dafidi lati joko lori itẹ ọba lori Oke Sioni ki o si jọba lori gbogbo awọn ẹya meji awọn enia rẹ̀. Dafidi ko dari ọrọ si Solomoni ọmọ rẹ̀ gẹgẹbi Oluwa mi,’ tabi si eyikeyi ninu awọn ọba Sioni ti o tẹle Solomoni titi lọ de ọdọ Ọba Sedekiah. Siwaju si i, ki iṣe Solomoni tabi eyikeyi ninu awọn ọba lori Oke Sioni li o jẹ alufa ati ọba, gẹgẹbi Melkisedeki ti jẹ.—2 Kronika 26:16-23.

20. Bawo ni ẹni asọtẹlẹ yi, biotilẹjẹpe ọmọ Dafidi ni, ṣe le jẹ ‘’Oluwa’‘ Dafidi sibẹ?

20 Biotiwukiori, niwọnbi alakoso ti a ṣeleri ti nilati jẹ ‘‘ọmọ’‘ Ọba Dafidi, éṣe ti Dafidi yio fi tọka si i gẹgẹbi ‘‘Oluwa mi’‘? Eyiyi jẹ nitori otitọ na pe ọmọ Dafidi’‘ titayọ yi yio jẹ ọba kan ti o ga ju Dafidi. Biotilẹjẹpe Dafidi joko lori ‘‘itẹ Jehofah’‘ lori Oke Sioni lori ilẹ aiye, on ko tilẹ, pápá nigba iku rẹ̀, goke re ọrun ki o si joko ‘‘li ọwọ ọtun’‘ Jehofah. Ṣugbọn ẹni na ti yio di ‘‘Oluwa’‘ Dafidi yio ṣe bẹ. Ipo ọba rẹ̀ li ọwọ ọtun Jehofah li ọrun li a le tọka si gẹgẹbi Oke Sioni li ọrun nitori a fi Oke Sioni ti ori ilẹ aiye ṣapẹrẹ rẹ̀, eyiti o ti fi igbakanri wà lárin awọn ogiri Jerusalemu ṣugbọn ti kò si mọ loni. Gẹgẹbi Jehofah funrarẹ̀ ti wi, ninu Orin Dafidi 89:27, nipa ti Messiah na: ‘‘Emi o si ṣe e li akọbi, ẹni giga ju awọn ọba aiye lọ.’‘ Ki iṣe oluwa Ọba nikan li on yio jẹ ju Dafidi, ṣugbọn on yio jẹ ‘‘alufa’‘ Ọlọrun Ọga Ogo titi lai, bi Melkisedeki ọba Salemu igbánì.—Orin Dafidi 76:2

21. Eṣe, nigbana, ti orukọ Abrahamu fi nilati di nla?

21 Diẹ ni Abrahamu baba-nla na, nigbana lọhun ni ọgọrun ọdun lọna ogun B.C.E., mọ pe ‘‘awọn ọba’‘ẹniti on ati aya rẹ̀ Sara nilati jẹ baba-nla fun yio kan ọba Messiah na ẹniti Melkisedeki ṣapẹrẹ rẹ̀, ẹniti Abrahamu san idemẹwa fun ninu gbogbo ikogun rẹ̀. Abajọ ti orukọ Abrahamu fi nilati di nla nitori isopọ rẹ̀ pẹlu iru Ọba ati Alufa bẹ! Abajọ ti o fi jẹ pe, nipasẹ Ọba ati Alufa yi ti o dabi Melkisedeki, ni gbogbo idile aiye yio ti bukun ara wọn tabi ri ibukun gba nipasẹ Abrahamu!—Genesisi 12:3.

“Ọ̀RẸ́” ỌLỌRUN

22. Bawo ni Ọlọrun ṣe fihan pe orilẹ-ede Rẹ̀ ti on yan nilati wá nipasẹ ọmọ ati ajogun Abrahamu nipa ti ara?

22 Lẹhin ijakadi oniṣẹgun ti Abrahamu ṣe si awọn ọba agboguntini mẹrin na, Ọlọrun ṣeleri fun Abrahamu ábò ti o nfẹ ati pẹlu pe ‘‘ajogun’‘ rẹ̀ yio jẹ ọmọ rẹ̀ niti ẹ̀dá. Pe orilẹ-ede ti Ọlọrun yan yio de nipasẹ ọmọ yi ati ajogun, Ọlọrun mu u dá Abrahamu loju nipasẹ apejuwe kan: ‘‘O si mu u jade wa si gbangba, o si wipe, Gboju wo oke ọrun nisisiyi, ki o si kà irawọ bi iwọ ba le kà wọn: o si wi fun u pe, Bẹni iru-ọmọ rẹ yio ri. O si gba (Jehofah) gbọ; on si ka a si fun u li ododo.’‘—Genesisi 15:1-6.

23. Lori ipilẹ wo li a gba kà Abrahamu si olododo, ki si ni ohun ti o li ẹtọ si?

23 Ẹ maṣe jẹki a gbagbe pe, li akoko yi, Abrahamu ṣi jẹ Heberu ti a koiti kọ ni ila sibẹ. Nitorina, a ko le kà a si olododo nitori ikọla rẹ̀ nipa ti ara; a kà a si fun u nitori igbagbọ rẹ̀ ninu Jehofah, ẹniti o nfi apakan ete rẹ̀ han fun Abrahamu. Nitorina a kà Abrahamu si olododo niwaju Ọlọrun; nipa bayi a kà a yẹ lati jẹ ọ̀rẹ́ Jehofah Ọlọrun. Ọpọ ọgọrun ọdun lẹhinna Ọba Jehoṣafati ti Jerusalemu pe Abrahamu ni ọ̀rẹ́ tabi ‘‘olufẹ’‘ Jehofah. Sibẹ lẹhinna, nipasẹ woli Isaiah, Jehofah sọrọ nipa rẹ̀ gẹgẹbi ‘‘Abraham ọ̀rẹ́ mi.’‘ (2 Kronika 20:7; Isaiah 41:8) Eyiyi fihan bi o ti niyelori to, bi o ti ṣe pataki to, igbagbọ ninu Jehofah ti o ni iṣe pẹlu ‘‘iru-ọmọ’‘ rẹ̀ nitotọ.

24. Bawo ni Abrahamu ṣe di baba fun Iṣmaeli, ati lẹhinna bawo ni o ṣe jẹ baba fun Isaaki?

24 Li ọdun 1932 B.C.E., nipasẹ imọran Sara aya rẹ̀ arugbo, ti o ti yàgàn, Abrahamu ni ọmọ kan lọdọ Hagari ẹrubirin rẹ̀ lati Egipti o si pe orukọ ni Iṣmaeli. (Genesisi 16:1-16) Ọdun mẹtala lẹhinna, ni 1919 B.C.E. Jehofah sọ fun Abrahamu pe kì iṣe Iṣmaeli ni yio ṣiṣẹ gẹgẹ bi “iru-ọmọ” tôtọ, ṣugbọn yio jẹ ọmọ kan lati ọdọ aya rẹ̀ Sara li ao ti yan “iru-ọmọ” na. Yio jẹ ọmọ kan lati ọdọ ominira obirin. Nitorina, ni ọdun ti o tẹle e, a bi Isaaki nigbati Sara jẹ ẹni adọrun ọdun. “Abrahamu si jẹ ẹni ọgọrun ọdun nigbati a bi Isaaki ọmọ rẹ̀ fun u.” Ni ọjọ kẹjọ igbesi aiye, a kọ Isaaki ni ila, gán gẹgẹbi Abrahamu baba rẹ̀ ti jẹ li ọdun ti o ṣaju gan.—Genesisi 21:1-5.

25. Kini akọsilẹ fihan niti boya Jehofah mu orilẹ-ede kan jade ti o kan gbogbo awọn ọmọ Abrahamu nipa ti ara?

25 O dùn mọ ni lati ṣakiyesi pe Ọlọrun ko mu orilẹ-ede kan jade nisisiyi lati inu awọn ọmọ rẹ̀ meji, Ismaeli akọbi ati Isaaki, orilẹ-ede kan ti o ni ẹyọ meji. Bẹkọ, ṣugbọn ọdun marun lẹhinna, nitori ohun ti Sara aya rẹ̀ nfẹ ni kanjukanju, Abrahamu lé Hagari ati ọmọ rẹ̀ Iṣmaeli kuro ninu ile rẹ̀ lati wá nkan ṣe fun ara wọn, lati lọ si ibikibi ti o ba wù wọn lati lọ. (Genesisi 21:8-21) Bẹni ki iṣe lẹhinna, lẹhin iku Sara ni 1881 B.C.E., ni Abrahamu mu orilẹ-ede kan jade lati inu orilẹ-ede ẹlẹya meje ti o jọ ti Isaaki ati awọn ọmọ miran ti Abrahamu bi nipasẹ Ketura, àlè kan. “Abrahamu si fi ohun gbogbo ti o ni fun Isaaki. Ṣugbọn awọn ọmọ àlè ti Abrahamu ní, Abrahamu bùn wọn li ẹbun, o si ran wọn lọ kuro lọdọ Isaaki, ọmọ rẹ̀, nigbati o wà láyé, si iha ila-ôrùn, si ilẹ ila-ôrùn.”—Genesisi 25:1-6.

26. Fun ifihan igbagbọ ti o gbamuṣe wo ni Abrahamu ṣe ri ,akanṣe ibukun gba ni ilẹ Moria, kini o si wi?

26 Ifihan igbagbọ ti o gbamuṣe gán ti Abrahamu fihan li o fa ibukun nlanla fun ‘‘ọ̀rẹ́’‘ Jehofah yi. O de lẹhin idanwo lile koko kan fun igbagbọ Abrahamu ati igbọran si Ọlọrun Ọga Ogo. Ibukun itẹwọgba atọrunwa li a kede rẹ̀ li ori oke kan ni ilẹ Moria, ibiti ọpọlọpọ ro pe o jẹ ibiti Ọba Solomoni kọ́ tempili Jehofah ologo na si ni ọpọ ọgọrun ọdun lẹhinna. (2 Kronika 3:1) Nibẹ, nibiti Jehofah yàn, ati lori igi ti a tẹ sori pẹpẹ okuta ti a ṣẹṣẹ gbé, ni a gbe ọdọmọkunrin kan si. Isaaki ni. Lẹba pẹpẹ na ni Abrahamu baba rẹ̀ duro pẹlu ọbẹ mẹ̀dúmbú li ọwọ rẹ̀. O mura tan lati pa aṣẹ Ọlọrun mọ lati pa Isaaki fun irubọ ki o si fii ru ẹbọ sisun si Ọlọrun ẹniti o fun u li ọmọ na lọna iyanu. Nigbana:

“Angeli (Jehofah) nì si kọ si i lati ọrun wá, o wipe, Abrahamu, Abrahamu: . . . Maṣe fọwọkan ọmọde nì, bẹni iwọ ko gbọdọ se e ni nkan: nitori nisisiyi emi mọ pe iwọ bẹru Ọlọrun, nigbati iwọ ko ti dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo . . . Angeli (Jehofah) nì si kọ si Abrahamu lati ọrun wa lẹrinkeji, o si wipe, Emi tikalami ni mo fi bura, ni (Jehofah) wi, nitori bi iwọ ti ṣe nkan yi, iwọ ko si dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo: pe ni bibukun emi o bukun fun ọ, ati ni bibisi i emi o mu iru-ọmọ rẹ bisi i bi irawọ oju-ọrun ati bi iyanrin eti okun; iru-ọmọ rẹ ni yio si ni ẹnubode awọn ọta wọn; ati ninu iru-ọmọ rẹ li ao bukun fun gbogbo orilẹ-ede aiye: nitori ti iwọ ti gba ohun mi gbọ.’‘—Genesisi 22 :1-18.

27. Kini ọrọ atọrunwa na fihan niti yiyan ‘‘iru-ọmọ’‘ na ati niti riri ibukun gba nipasẹ rẹ̀?

27 Eyiyi tumọsi pe ‘‘iru-ọmọ’‘ na ti a ṣeleri nipasẹ ẹniti gbogbo orilẹ-ede yio ri ibukun gba yio de nipasẹ ila idile Isaaki. Nipa bẹ Jehofah Ọlọrun fihan pe on nṣe yiyan ila idile na, ati pe gbogbo awọn arakunrin Isaaki ki yio ni ipa kankan ninu pipese ‘‘iru-ọmọ’‘ na. Sibẹsibẹ, awọn orilẹ-ede ti o jade wa lati inu awọn arakunrin Isaaki le ri gba fun ara wọn ibukun nipasẹ ‘‘iru-ọmọ’‘ na. Gbogbo orilẹ-ede loni, eyini ni, awọn enia ti mbẹ ninu awọn orilẹ-ede loni, le ri gba bakanna, ibukun nipasẹ ‘‘iru-ọmọ’‘ na.

28. Ṣemu waláye to lati kọ nipa awọn ohun ti o ṣẹlẹ wo ti o jẹmọ ila idile rẹ̀?

28 Baba-nla na Ṣemu, oluré ikun-omi agbaiye na kọja, waláye lati kẹkọ nipa ibukun atọrunwa na ti a kede sori Abrahamu; niti tôtọ, Ṣemu waláyé lati mọ nipa igbeyawo Isaaki pẹlu Rebeka ẹlẹwa lati Harani ni Mesopotamia. Ṣemu waláyè titi di 1868 B.C.E., ọdun mẹwa lẹhin igbeyawo na, ṣugbọn ko waláyè lati ri awọn ọmọ igbeyawo na. Ṣugbọn Abrahamu ṣe bẹ.—Genesisi 11:11; 25:7.

[Ibeere]