Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Yíyàn Atọrunwa na Ni Ibamu pẹlu ‘‘Ete Aiyeraiye”

Yíyàn Atọrunwa na Ni Ibamu pẹlu ‘‘Ete Aiyeraiye”

Ori 8

Yíyàn Atọrunwa na Ni Ibamu pẹlu ‘‘Ete Aiyeraiye”

1. Ibere wo li o dide niti ọmọ ọkunrin na ẹniti Ọlọrun tun sọ ileri majẹmu rẹ̀ fun?

JEHOFAH ỌLỌRUN yan lati sọ di ọtun fun Isaaki majẹmu ileri ti a ṣe fun baba rẹ̀. Abrahamu. (Genesisi 26:1-5, 23, 24) Biotilẹjẹpe o gbeyawo nigbati o di ẹni ogoji ọdun, Isaaki nilati di ẹni ọgọta ọdun ki o to ni ọmọ—ibeji. Jehofah, ẹniti o dahun adura Isaaki fun ọmọ bibi, yio ha ṣe yiyan kan niti awọn ọmọ ibeji ọkunrin wọnni bi?

2. Bawo ni Jehofah ṣe fihan ewo ninu awọn ibeji na ti on yio yan?

2 Jehofah fi yiyan rẹ̀ han nigba iloyun Rebeka lẹhinti o ti gbadura ti o si bere lọwọ rẹ̀ nipa awọn ọmọ rẹ̀: ‘‘[Jehofah] si wi fun u pe, orilẹ-ede meji ni mbẹ ninu rẹ, irú enia meji ni yio yà lati inu rẹ: awọn enia kan yio le ju ekeji lọ; ẹgbọn ni yio si má sìn aburo.’‘ Esau li o jẹ akọbi, ti Jakobu si jẹ abikẹhin ninu ibeji na. (Genesisi 25:20-23) Nipa bayi Jehofah fihan pe on ko ni mu orilẹ-ede kan jade lati inu awọn ibeji ọmọ Isaaki wọnyi, orilẹ-ede kan ẹlẹya meji. Kakabẹ, orilẹ-ede meji li o nilati wà, pẹlu awujọ orilẹ-ede kan lati ọdọ ẹniti o dagba ju ninu ibeji na ti yio di alailagbara ti yio si ma sìn awujọ orilẹ-ede ẹniti o kereju ninu ibeji na. Eyiyi ṣe iyipada ninu ẹtọ ti ẹ̀dá tí akọbi ọmọ má nní lati di ẹni pataki ju. Nipa bayi Jehofah fihan ẹniti on yio yàn.

3. Yiyan nibẹ ha simi lori awọn iṣẹ enia tabi lori ẹni na ti o ṣe pipè na?

3 Olodumare, Ọlọrun Alagbara-Gbogbo na lí ẹtọ lati ṣe eyi, ni ibamu pẹlu ete rẹ̀ fun bibukun gbogbo araiye. Nipa eyi, alalaye kan lori Bibeli ni ọgọrun ọdun ekini kọwe: ‘‘Ki si iṣe kiki eyi; ṣugbọn nigbati Rebeka pẹlu loyun fun ẹnikan, fun Isaaki baba wa; nitori nigbati a ko ti ibi awọn ọmọ na, bẹni nwọn ko ti iṣe rere tabi buburu, (ki ipinnu Ọlọrun nipa ti ayanfẹ ki o le duro, ki iṣe nipa ti iṣẹ, bikoṣe ti ẹni ti npe-ni;) a ti sọ fun u pe, Ẹgbọn ni yio má sìn aburo. Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Jakobu ni mo fẹran, ṣugbọn Esau ni mo korira.’‘—Romu 9:10-13; ti a fayọ pẹlu lati Malaki 1:2, 3.

4. Eṣe ti Jehofah ni ifẹ ti o dinku fun Esau ju ti Jakobu, pápá ṣaju ki a to bi wọn?

4 Dajudaju Olodumare, Ọlọrun Alagbara-Gbogbo ko ṣe yiyàn buburu. Laisi aniani On, nitoriti o le mọ iṣiṣẹ ẹyin-ọmọ ibeji ti mbẹ ninu Rebeka, ti ri tẹlẹ bi awọn ọmọdekunrin na yio ṣe huwa ninu idari igbesi aiye wọn. Nitorina o yan eyiti o tọ ninu ibeji na, biotilẹjẹpe ẹni yi jẹ aburo ninu ibeji na. Laibikita fun yiyan rẹ̀ ni ibamu pẹlu rẹ̀, Jehofah ko fi agbara mu awọn nkan. On ko wewe fun Esau ti o dagba ju lati ta ogún ìbí rẹ̀ fun iwọn ipẹtẹ kekere kan lasan fun Jakobu aburo rẹ̀ li ọjọ ti o le koko fun ipinnu. O ṣe kedere, biotiwukiori, pe Jehofah ti ri i tẹlẹ pe Esau ti a ko ti ibi na ko ní imọriri ati ifẹ fun ohun ti ẹmi gẹgẹ bi Jakobu yio ti ni. Nitori idi eyi on ni ifẹ ti o dinku fun Esau ju ti Jakobu o si ṣe yiyan rẹ̀ bẹ gẹgẹ, ani nigbati awọn ibeji na ṣì wà sibẹ laibi ninu iya wọn.—Genesisi 25:24-34.

5. Jehofah ha wewe bi Jakobu yio ṣe ri ibukun ti Isaaki sọrọ rẹ̀ gba, On ha si yi i pada bi?

5 Jehofah ko wewe ọgbọn ẹ̀wé ti Jakobu ati iya rẹ̀ Rebeka lò nikẹhin niti gbigba ibukun ti Isaaki sọ jade, ṣugbọn Jehofah yọda fun Isaaki afọju arugbo na lati kede ibukun ogún ìbí na sori Jakobu, niwọnbi Jakobu ti yẹ lati gba a. (Genesisi 27:1-30) Jehofah ko yọda fun Isaaki lati yi ibukun na pada, ṣugbọn, nigbati Jakobu nsa lọ kuro lọwọ ibinu onikupani lati ọdọ Esau arakunrin ibeji rẹ̀, Ọlọrun fi ète tẹ ibukun Isaaki lori Jakobu. Eyiyi ṣe itẹwọgba yiyan ti Ọlọrun yan Jakobu ṣaju bibi rẹ̀. Bawo ni?

6. Bawo li a ṣe ṣe itilẹhin fun yiyan ti Ọlọrun yan Jakobu ninu àlá ti Jakobu lá nipa ti àkàsọ̀ ti awọn angeli nlo?

6 Nibiti a npe ni Beteli ni Ilẹ Ileri, Jakobu isansa na ‘‘si lá àlá, si kiyesi i, a gbe àkàsọ̀ kan duro lori ilẹ, ori rẹ̀ si de oke ọrun: si kiyesi i, awọn angeli Ọlọrun ngoke, nwọn si nsọkalẹ lori rẹ̀. Si kiyesi i, [Jehofah] duro loke rẹ, o si wi pe, Emi ni [Jehofah] Ọlọrun Abrahamu baba rẹ, ati Ọlọrun Isaaki: ilẹ ti iwọ dubulẹ le nì, iwọ li emi o fi fun, ati fun iru-ọmọ rẹ. Iru-ọmọ rẹ yio si ri bi erupẹ ilẹ, iwọ o si tan kalẹ si iha iwọ-orùn, ati si iha ila-orùn, ati si iha ariwa, ati si iha gusu: ninu rẹ, ati ninu iru-ọmọ rẹ li a o bukun fun gbogbo ibatan aiye. Si kiyesi i, emi wà pẹlu rẹ, emi o si pa ọ mọ ni ibi gbogbo ti iwọ nlọ, emi o si tun mu ọ bọwa si ilẹ yi; nitori emi ki yio kọ ọ silẹ, titi emi o fi ṣe eyiti mo wi fun ọ tan.’‘—Genesisi 28:12-15.

7, 8. (a) Ọrọ atọrunwa yi tumọsi kini fun ila idile Messiah na? (b) Ni iyatọ si Esau, Jakobu fi ara rẹ̀ han fun ijọsin tani?

7 Gẹgẹ bi ọrọ Ọlọrun yi ti ko le yipada ti ko si le ṣeke ti wi, Ileri Abrahamu ti a gbekalẹ ninu Genesisi 12:1-7 li a nilati muṣẹ lati ọwọ Ọlọrun nipasẹ iru-ọmọ tabi awọn atọmọdọmọ Jakobu.

8 Eyiyi tumọsi pe Messiah na, ‘‘iru-ọmọ’‘ ‘‘obirin’‘ Ọlọrun li ọrun, nilati wá nipasẹ ila idile Jakobu. Idi ni yì ti a fi gbájúmọ titẹle itan awọn ’orilẹ-ede ati awọn idile aiye ti nwọn yio bukun ara wọn sibẹ nipasẹ Messiah. ‘‘iru-ọmọ’‘ na. Pẹlupẹlu, Ọlọrun Abrahamu ati ti Isaaki li a tun npe ni ‘‘Ọlọrun Jakobu.’‘ Eyiyi li a ko le sọ fun Esau (tabi, Edomu), ẹniti ko jẹki a mọ̀ ọn yatọ ninu ijọsin Jehofah ati ẹniti awọn atọmọdọmọ rẹ̀ di awọn ọta olusin Jehofah. Oriṣa na Qos ni ’ọlọrun Edomu.’ (2 Kronika 25:14; Esekieli, ori karundinlogoji) Tempili ti a kọ lẹhinna ni Jerusalemu wá di ohun ti a npe ni ‘‘ile Ọlọrun Jakobu.’‘ (Isaiah 2:3) Gẹgẹbi apẹrẹ kan fun wa nisisiyi ni awọn akoko iṣoro wọnyi, onipsalmu na ti a misi wipe: ‘‘[Jehofah] awọn ọmọ-ogun wà pẹlu wa; Ọlọrun Jakobu li ábò wa.’‘‘—Orin Dafidi 46:11.

YIYAN ẸYA ỌBA NA

9. (a) Eṣe ti a fi npe awọn atọmọdọmọ Jakobu ni awọn ọmọ Israeli? (b) Nibo ni Jakobu ti di baba fun ekejila ninu awọn ọmọ rẹ̀?

9 Nigbati o wà ni Paddan-aramu ni afonifoji Mesopotamia fun ogún ọdun, Jakobu gbeyawo ninu ibatan idile tí Isaaki baba rẹ̀ tẹwọgba o si di baba fun ọmọ mọkanla. Nigbana li Ọlọrun sọ fun u pe ki o pada si Ilẹ Ileri, lati ibiti on ti sa lọ. (Genesisi 31:3) Nigbati Jakobu npadabọ ninu irin-ajo rẹ̀ li a fun u ni àpélé orukọ na Israeli. Angeli Ọlọrun wi fun u pe: A ki yio pe orukọ rẹ ni Jakobu mọ, bikoṣe Israeli: nitoripe, iwọ ti ba Ọlọrun ati enia jà, iwọ si bori.’‘ (Genesisi 32:28) Lati igbana li a ti npe awọn atọmọdọmọ Jakobu ni awọn ọmọ Israeli. (Eksodu 17:11) Lẹhinna, nigbati Jakobu tabi Israeli wà li ọna rẹ̀ padabọ lati ibiti o ti ṣe ibẹwo si Beteli, nibiti on ti lá àlá àkàsọ, o di baba fun ọmọ rẹ̀ ekejila, Benjamini. Ṣugbọn nigbati Rakeli aya ayanfẹ Jakobu mbi ọmọ rẹ̀ ekeji yi, o kú. Gẹgẹ bi a ti ṣe kọ ọ silẹ ninu Genesisi 35:19, ‘‘Rakeli si kú, a si sin i li ọna Efrata, ti iṣe Betlehemu.’‘

10. Nigba atipo siwaju si i Jakobu ni Ilẹ Ileri, iru awọn ohun-ti-ko-muni-yẹ wo ni Reubeni bọ si abẹ rẹ̀?

10 Lẹhinti Jakobu pada si Ilẹ Ileri ni 1761 B.C.E., o mba a lọ lati gbe ibẹ gẹgẹ bi alejo kan fun ọdun mẹtalelọgbọn. Li akoko na ọpọ ohun pataki ṣẹlẹ, ṣugbọn ki iṣe gẹgẹ bi iwewe kankan lati ọdọ Ọlọrun. Isaaki, baba Jakobu, kú nigbati o di ẹni ọgọsan ọdun. (Genesisi 35:27-29) Reubeni, ọmọ Jakobu ti o dagba ju, ba Bilha àlè baba rẹ̀, ọmọ-ọdọ obirin Rakeli, sùn. (Genesisi 35:22) Eyiyi fagile Reubeni lati gbadun ẹtọ akọbi fun baba rẹ̀ Jakobu ati lati ni Messiah ọba na nipasẹ ila idile rẹ̀. Dajudaju ki iṣe Jehofah Ọlọrun li o seto eyi, nitoripe On ko lọwọ ninu iru ibalopọ alagbere bẹ.—Genesisi 49:1-4.

11, 12, (a) Bawo ni Simeoni ati Lefi ṣe sọ ara wọn di alaiyẹ ninu anfani niti idile Messiah na? (b) Kini Ọlọrun gbọdọ ṣe nisisiyi niti yiyan na?

11 Ki Rakeli to kú ati ki Reubeni to huwa agbere rẹ̀ bibanileru, Dina ọmọbirin Jakobu li a ti bajẹ lọna ibalopọ takọtabọ lati ọwọ olugbe Ilẹ Ileri kan, ti a npe ni Ṣekemu ọmọkunrin Hamori ara Hiffi, ẹniti o ngbe ni ilu Ṣekemu. Ibinu nlanla li o wà lárin awọn ọmọ Jakobu nitoripe o ṣe ‘‘ohun buburu’‘ yi ‘‘ni Israeli.’‘ Nitorina, nigbati a sọ awọn ọkunrin olugbe Ṣekemu di alailagbara nitoripe nwọn faramọ ohun ti a nbere niti ikọla, Simeoni, ekeji ninu ọmọ Jakobu ati Lefi ẹkẹta ninu ọmọ rẹ̀ mu ida nwọn si pa awọn ọkunrin ara Ṣekemu wọnni ti ko fura ni ipa-kupa, lẹhin eyiti a pa ilu na run.

12 Jakobu gẹgẹbi woli Ọlọrun ko tẹwọgba iwa ipa yi. O sọ fun Simeoni ati L,efi pe nwọn ti tipa bẹ sọ on di ‘‘òrùn ninu awọn onilẹ’‘ nwọn si ti fi on ati awọn ara ile on fun pipa lati ọwọ awọn enia ti o pọ julọ ninu ilẹ na. (Genesisi 34:1-30) Nitori iru ipakupa oníkà bẹ ninu ibinu ati iyara-kánkán, Simeoni ati Lefi fagile ara wọn yala ki ọkan ninu wọn ní ila idile na eyiti yio mu Messiah ‘‘iru-ọmọ’‘ na jade. Nitorina anfani ọlọla yi nilati lọ sọdọ ọmọ miran nisisiyi yatọ si Simeoni ati Lefi ati Reubeni ọmọ ti o jẹ akọbi na niti iwa ẹ̀dá. (Genesisi 49:5-7). Dajudaju Jehofah Ọlọrun ko wewe awọn ọran lọna bẹ. Nisisiyi on nilati mu ara rẹ̀ ba awọn ipo titun ti o ṣẹṣẹ dide mu. Yiyan rẹ̀ larin awọn ọmọ Jakobu ti o ṣiku ni On yio fihan sibẹ nipasẹ woli rẹ̀, Jakobu tabi Israeli.

13, 14. Bawo ni Jakobu ati idile rẹ̀ ṣe di ẹniti o kô lọ si Egipti lati wà pẹlu Josefu nibẹ?

13 Josefu akọbi Rakeli, aya keji ẹniti iṣe ayanfẹ fun Jakobu, li ikọkanla ninu idile na. Jakobu fi akanṣe ifẹ han si ọmọ ogbé rẹ̀ yi. Nitori idi eyi awọn arakunrin Josefu bẹrẹsi jowu rẹ̀. Laihan si baba wọn, nwọn dọgbọn lati tà Josefu fun awọn oniṣowo ti nkọja lọ ti nwọn nlọ si Egipti. Nwọn mu ki Jakọbu baba wọn gbagbọ pe ẹranko buburu ti pa Josefu jẹ.

14 A ta Josefu si oko ẹrú ni Egipti, ṣugbọn nipaṣẹ ojurere Ọlọrun na ẹniti on nsin tọkantọkan ti o si nṣe igbọran si, a gbe e ga si ipo alabojuto onjẹ ati olotu ijọba ni Egipti labẹ Farao. Li ọdun 1728 B.C.E. a pari ija larin Josefu ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn ẹniti o wá si Egipti fun onjẹ ni akoko ìyàn agbaiye. Lẹhinna, nipasẹ awọn eto ti Josefu ṣe, baba rẹ̀ Jakobu tabi Israeli lọ si Egipti pẹlu gbogbo idile rẹ̀ nwọn si tẹdo si ibiti a npe ni Ilẹ Goṣeni. Nibẹ ni Jakobu si ngbe fun ọdun mẹtadinlogun.—Genesisi, ori 37-47.

15, 16. Jakobu wọ Egipti sibẹ lati jẹ ajogun kini, bawo li a si ti ṣe pe afiyesi si eyi ninu Orin Dafidi 105:7-15?

15 Itọni Ọlọrun li o mu ki Jakobu fi Ilẹ Ileri silẹ ti o si sọkalẹ lọ si Egipti lati dahun ipe Josefu. (Genesisi 46:1-4) On sọkalẹ lọ sibẹ gẹgẹbi ajogun Ileri Abrahamu sibẹ ati ẹni na ti yio ta atare rẹ̀. Orin Dafidi 105:7-15 tọkasi otitọ yi o si wipe:

16 ‘‘[Jehofah], on li Ọlọrun wa: idajọ rẹ̀ mbẹ ni gbogbo aiye. O ti ranti majẹmu rẹ̀ lailai, ọrọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran; majẹmu ti o bá Abrahamu dá, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki; o si gbe eyi na kalẹ li ofin fun Jakobu, ati fun Israeli ni majẹmu aiyeraiye; Pe, iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun; ipin ilẹ-ini nyin; nigbati o ṣe pe kiun ni nwọn wà ni iye; nitotọ, diẹ kiun, nwọn si ṣe alejo ninu rẹ̀; nigbati nwọn nlọ lati orilẹ-ede de orilẹ-ede, lati ijọba kan de ọdọ awọn enia miran. On ko jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni iwọsi: nitotọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn; Pe, ẹ maṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi [li ede Heberu ọpọ iye ma-shiʹahh, tabi awọn messiah], ki ẹ má si ṣe awọn woli mi ni ibi.’‘—Kika eti iwe.

17. Eṣe ti Jehofah fi sọrọ nipa Abrahamu, Isaaki ati Jakobu gẹgẹ bi ‘‘woli’‘ ati gẹgẹ bi ‘‘ẹni ami ororo’‘ rẹ̀?

17 Nipa bayi Jehofah pe Abrahamu, Isaaki ati Jakobu ni awọn woli rẹ̀, nitôtọ bẹ ni nwọn si jẹ. (Genesisi 20:7) A le sọ pe woli kan jẹ ẹni-ororo nitori pipẹ̀ ti a pe e ati yiyàn ti a yàn a, ani laisi tita ororo oyè le e lori. (1 Awọn Ọba 19:16, 19; 2 Awọn Ọba 2:14) Bẹ gẹgẹ, biotilẹjẹpe a ko ta ororo sori Abrahamu, Isaaki ati Jakobu li ọna ti Jakobu gba ta ororo si òpó na li ori nibiti a npe ni Beteli, a pe wọn li ‘‘ẹni-ororo! bi o ti yẹ nitori ihuwasi Jehofah si wọn. Genesisi 28:18, 19; 31:13) Otitọ na pe Jehofah pe wọn ni ‘‘ẹni-ororo mi’‘ fihan pe on yàn wọn. Itumọ Bibeli ti Moffatt sọ ninu Orin Dafidi 105:15 pe: ’’Maṣe fi ọwọ kan ayanfẹ mi, maṣe pa awọn woli mi lara.’‘ (Pẹlupẹlu 1 Kronika 16:22) Jehofah nyàn awọn ẹniti on ba fẹ; ete kan wà lẹhin yiyan rẹ̀.

18. Bẹ gẹgẹ, bawo li a ṣe pe orilẹ-ede na ti yio jade nipasẹ Abrahamu, Isaaki ati Jakobu, esitiṣe ti o fi ba a mu gẹ?

18 Abrahamu, Isaaki ati Jakobu jẹ ‘‘awọn messiah’‘ Jehofah, o si wà ni ibamu pẹlu eyi pe orilẹ-ede Messiah na wá nipasẹ wọn. Iwe Mimọ sọrọ nipa orilẹ-ede ti a yàn yi gẹgẹbi ‘‘messiah’‘ tabi ‘‘ẹni-ororo’‘ Jehofah. Ninu Orin Dafidi 28:8, 9, onipsalmu na Dafidi wipe: [Jehofah] li agbara wọn, On si li agbara igbala ẹni-ororo [Heberu: ma-shi-ahh] rẹ̀. Gba awọn enia rẹ la, ki o si busi ilẹ-ini rẹ: má bọ wọn pẹlu, ki o si má gbe wọn leke lailai.’‘ Lẹhinna, woli na Habakkuku wi fun Jehofah ninu adura pe: ‘‘Iwọ jade lọ fun igbala awọn enia rẹ, fun igbala ẹni ami ororo [ma-shi-ahh] rẹ.’‘ (Habakkuku 3:13) O wà ni ibamu pẹlu otitọ yi pe, nipasẹ awọn enia ‘‘ẹni ami ororo’‘ tabi orilẹ-ede, Messiah tôtọ kan, ‘‘iru-ọmọ’‘ ‘‘obirin’‘ Ọlọrun li ọrun yio de li akoko ti Ọlọrun yàn.—Genesisi 3:15.

19. Nitori jijẹ awọn olori ẹya mejila, kini a npe awọn ọmọ Jakobu?

19 Ni Egipti li awọn atọmọdọmọ Jakobu ti di ọpọlọpọ enia, ti nwọn muratan lati di orilẹ-ede. Nigba akoko na ni Jakobu wa lori akete iku rẹ̀ (ni 1711 B.C.E.) ti o si sọ awọn ọrọ idagbere fun awọn ọmọ rẹ̀ ti a fi wipe: ’’Gbogbo wọnyi li awọn ẹya Israeli mejila: eyi ni baba wọn si sọ fun wọn, o si sure fun wọn; olukuluku bi ibukun tirẹ̀, li o sure fun wọn.’‘ (Genesisi 49:28) Nitoripe ọkọkan ninu wọn di olori ẹya kan, awọn ọmọ Jakobu mejila wọnyi li a npe ni ‘‘awọn baba-nla,’‘ tabi ’olori awọn baba. Gẹgẹbi asọrọ kan niwaju Sanhedrin Jerusalemu ti wi nigbakanri: ‘‘O si fun u ni majẹmu ikọla: bẹli Abrahamu bí Isaaki, o kọ ọ ni ila ni ijọ kẹjọ: Isaaki si bí Jakobu; Jakobu si bí awọn baba nla mejila. Awọn baba nla si sẹ ilara Josefu, nwọn si tà a si Egipti: ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.’‘ (Iṣe 7:8, 9, New English Bible) Bi o ti tọ, awọn Ju ti nsọ ede Griki sọrọ nipa ‘‘Abrahamu baba nla,’‘ ati pẹlu nipa ‘‘Dafidi baba nla.’‘ Heberu 7:4; Iṣe 2:29, NEB.

20. A ha gbe baba nla niti isin kalẹ nipa bayi ni Israeli bi?

20 Eyi ko tumọsi, biotiwukiori, pe a gbe baba nla ti isin kan kalẹ lárin awọn atọmọdọmọ Jakobu nibẹ ni Egipti. Lẹhin iku Jakobu ni ilẹ Goṣeni, Josefu gẹgẹbi olotu ijọba Egipti fun Farao ko gbe ara rẹ̀ kalẹ gẹgẹbi baba nla olori ‘‘awọn ẹya Israeli mejila,’‘ biotilẹjẹpe awọn ọrọ ibukun ikẹhin lati ẹnu baba rẹ̀ le e lori fihan pe ẹto akọbi li a ti ta atare rẹ̀ sọdọ Josefu.—Genesisi 49: 22-26; 50: 15-26.

21. (a) Jakobu fihan pe ẹtọ ọmọ akọbi li a ti ta atare rẹ̀ si tani nisisiyi? (b) Yiyan ẹni olori na ninu ila idile ti o yọrisi Messiah ọba na simi lori tani?

21 Nipa awọn ibukun alasọtẹlẹ rẹ̀ sori awọn ọmọ rẹ̀ mejila Jakobu baba nla na fihan ohun ti o ju ẹtọ ìbí tabi ẹtọ akọbi eyiti a ti ta atare rẹ̀ lati ọdọ Reubeni, ọmọ akọbi Jakobu lati ọdọ iyawo rẹ̀ akọkọ, Lea, fun Josefu, akọbi Rakeli iyawo rẹ̀ ekeji. (Genesisi 29: 21-32) Ṣaju tita Josefu si oko ẹrú ni Egipti, awọn arakunrin rẹ̀ lodi si ero na pe on le di ọba le wọn lori. (Genesisi 37:8) Ṣugbọn tipẹtipẹ ṣáju eyi, nigbati Ọlọrun fun Abrahamu baba nla na ni majẹmu ikọla, Ọlọrun sọtẹlẹ pe awọn ọba yio ti inu Abrahamu jade, eyi yio si jẹ nipasẹ aya rẹ̀ Sara, orukọ ẹniti Ọlọrun yipada lati Sarai si Sara, ti o tumọsi ‘‘Ọmọ Ọba.’‘ (Genesisi 17:16) Pẹlupẹlu, nigbati Ọlọrun yí orukọ Pg 97Jakobu pada si Israeli, o ṣeleri pe awọn ọba yio ti inu Jakobu jade wa. (Genesisi 35:10, 11) Ṣugbọn, ẹtọ ọmọ akọbi ninu idile ko gbérù lẹsẹkẹsẹ pẹlu rẹ̀ ẹtọ ati ọla lati jẹ baba nla fun ila awọn ọba ti yio yọrisi Ọba Messiah, ‘‘iru-ọmọ’‘ ‘‘obirin’‘ Ọlọrun li ọrun. Ọran pataki yi simi lori yiyàn Ọlọrun. On mu ki Jakobu tọkasi ewo ni ọmọ na ti yio di baba nla fun iru Ọba bẹ.

22. Ninu ibukun kan, lori ọmọ ewo ni Jakobu tọka ‘‘ọpa alade’‘ si ati ‘‘ọpa aṣẹ’‘?

22 Lẹhin fifi ilodisi rẹ̀ si Reubeni, Simeoni ati Lefi han, Jakobu ti nku lọ na wi ni itọkasi ọmọ rẹ̀ ẹkẹrin lati ọdọ Lea iyawo rẹ̀ akọkọ pe: ‘‘Judah, iwọ li ẹniti awọn arakunrin rẹ yio ma yìn; ọwọ rẹ yio wà li ọrun awọn ọta rẹ; awọn ọmọ baba rẹ yio foribalẹ niwaju rẹ. Ọmọ kiniun ni Judah; ọmọ mi, ni ibi-ọdẹ ni ìwọ ti goke: o bẹrẹ, o ba bi kiniun, ati bi ogbo kiniun; tani yio lé e dide? Ọpa-alade ki yio ti ọwọ Judah kuro, bẹli olofin ki yio kuro lárin ẹsẹ rẹ̀, titi Ṣiloh yio fi de; on li awọn enia yio gbà tirẹ̀.’‘—Genesisi 49:8-10.

23. Gbogbo ami wọnni, ọpa alade, ọpa aṣẹ, igbọran gbogbo enia, ifiwera pẹlu kiniun, sọrọ kini nipa Judah?

23 jẹ ki a ṣakiyesi ifiwera Judah pẹlu kiniun ti Jakobu ṣe. Mika 5:8 fi kiniun we ọba ẹranko kan ninu igbo. Esekieli 19:1-9 fi awọn ọba ijọba Judah we awọn kiniun. Nitorina ifiwera Judah pẹlu kiniun ti Jakobu ṣe ṣe daradara pẹlu otitọ na pe ọpa alade na ‘‘ki yio ti ọwọ Judah kuro,’‘ eyiti o si tumọsi pe nisisiyi Judah ti ní ọpa alade na on ko si ni padanu rẹ̀ tabi ki a fi dù u. Pe eyi jẹ ọpa alade ijọba li a mu lagbara pẹlu otitọ na pe ọpa alade na li a sopọ mọ ’’ọpa aṣẹ,’‘ eyiti ko si ni ti ọwọ Judah kuro titi Ṣiloh yio fi de. Siwaju si i, fun Judah, gẹgẹbi Ṣiloh yi ti ṣapẹrẹ rẹ̀, ‘‘on li awọn enia yio gbọ́ tirẹ̀.’‘ (Genesisi 49:10) Gbogbo awọn àmì wọnyi nipa Judah sọrọ nipa jijẹ ọba!

24, 25. (a) Kini orukọ na Ṣiloh tumọsi, tani o si nsọrọ nipa rẹ̀? (b) Eṣe ti ọpa alade na ko fi ni ti ọwọ Judah kuro?

24 Orukọ na Ṣiloh li a loye pe o tumọsi ‘‘Ẹni Na Ti Iṣe Tirẹ̀.’‘ Latin Vulgate igbánì, eyiti a tumọ rẹ̀ lati inu itumọ Heberu ti mbẹ nigbana, ka pe: ‘‘Titi ẹniti ao ran yio fi de.’‘

25 Dídé Ṣiloh yi (Ẹni Na Ti Iṣe Tirẹ̀’‘) tọkasi ẹni kanna ẹniti a sọ asọtẹlẹ wiwá rẹ̀ ninu awọn ọrọ Jehofah Oluwa Ọba Alaṣẹ si ẹniti o kẹhin ninu awọn ọba Judah ti Jerusalemu: ‘‘Emi o bì i ṣubu, emi o bì i ṣubu, emi o bì i ṣubu; ki yio sì sí mọ, titi igbati ẹniti o ni i ba de; emi o si fi fun u.? (Esekieli 21:27) Laisi aniani eyiyi tọkasi wiwá Messiah Ọba na, ‘‘iru-ọmọ’‘ ‘‘obirin’‘ iṣapẹrẹ Ọlọrun, nitoripe pẹlu wiwá rẹ̀ ko tun si arọpo awọn ọba miran ti a nfẹ lẹhin rẹ̀. Nigbana ni ijọba ẹya Judah yio de ogogoro opin rẹ̀ ti yio si wà titi lai li ọwọ Siloh. Eyiyi ni Messiah Ọba na ti yio joko li ọwọ ọtun Jehofah li ọrun ti yio si jẹ ọba kan gẹgẹ bi ti Melkisedeki, ẹniti Abrahamu baba nla san idamẹwa awọn ikogun rẹ̀ fun. (Orin Dafidi 110:1-4) Nipa bayi ọpa alade ko ni ti ọwọ Judah kuro.

26. (a). Bawo ni 1 Kronika 5:1, 2 ṣe fi ẹtọ akọbi han pe o jẹ ohun kan ati tí awọn ohun ti o jẹmọ ti ọba si jẹ ohun miran? (b) Laibikita fun awọn iṣẹlẹ ti a ko wewe rẹ̀ tẹlẹ, Jehofah li ominira o si le ṣe kini?

26 Pe ẹ̀tọ́ ọmọ akọbi ninu idile jẹ ohun kan ati yiyan iṣẹ aṣaju bi ọba funni jẹ ohun miran, ati pe Ọlọrun nipasẹ Jakobu baba nla ti nku lọ na yan iṣẹ aṣáju bi ọba fun Judah li a sọ kedere ninu Iwe Mimọ. Ninu 1 Kronika 5:1, 2 a kà nipa awọn ọmọ Jakobu pe: ‘‘Njẹ awọn ọmọ Reubeni, akọbi Israeli, (on li akọbi; ṣugbọn, bi o ti ṣe pe o ba ẹní baba rẹ̀ jẹ́, a fi ogún ìbí rẹ̀ fun awọn ọmọ Josefu ọmọ Israeli: a ki yio si ka itan-idile [Reubeni] na gẹgẹ bi ipo ìbí, Nitori Judah bori awọn arakunrin rẹ̀, ati lọdọ rẹ̀ ni alaṣẹ ti jade wa [ọmọ ọba ọkunrin na si ti ọdọ rẹ̀ jade wá. (Leeser); lati ọdọ rẹ̀ ni ẹniti yio jẹ ọmọkunrin ọba si ti jade wá (Jewish Publication Society)]; ṣugbọn ogún ìbí jẹ ti Josefu.’‘ Awa ko le wi nihinyi pe Olodumare, Ọlọrun Ọlọgbọn-Gbogbo li o wewe rẹ̀ lọna bayi, nitoripe on ko lọwọ ninu awọn aṣemaṣe Reubeni, Simeoni ati Lefi ati awọn iyọrisi ti o ti inu rẹ̀ jade. Kakabẹ, ni iṣedede pẹlu ọna ti awọn iṣẹlẹ ti a ko wewe rẹ̀ tẹlẹ wọnyi gba ṣẹlẹ on li ominira lati ṣe yiyan Judah. Laibikita fun ohun ti o ti ṣẹlẹ o ṣéṣe fun u lati rò mọ ete rẹ̀ akọkọ ati lati mu u ki o ṣiṣẹ laisi iyipada.

27, 28. (a) Lori orilẹ-ede wo, nigbana, ni awa yio tẹ̀ oju wa mọ, ati sori apa wo nibẹ ni pataki? (b) Ni ṣiṣe iṣẹ lori ẹri ti Ọlọrun pese, awọn anfani wo li awa yio gbadun?

27 Awọn yiyàn Ọlọrun ati igbeṣe rẹ̀ nṣiṣẹ gẹgẹbi amọna ti o daju fun wa bi a ti nronu nipa ‘‘ete aiyeraiye’‘ Rẹ̀ eyiti on gbekalẹ niti Ẹni Ororo na, Messiah. Lati inu awọn ọrọ asọtẹlẹ eyiti on misi Jakobu baba nla ti nku lọ na lati sọ lori Judah, awa mọ̀ ọna fun wa. lati tẹle. Awa nilati tẹ oju wa, ki iṣe sori awọn ẹya Israeli mejila ni gbogbogbo lasan, bikoṣe sori ẹya Judah ni pataki nitori ibatan rẹ̀ táràtà pẹlu Messiah Jehofah, ‘‘iru-ọmọ’‘ ‘‘obirin’‘ Rẹ̀ li ọrun. Ẹri siwaju ati siwaju li o nkorajọ pelemọ lati ràn wa lọwọ lati mọ̀ Messiah Ọba yi ẹniti ‘‘ete aiyeraiye’‘ Ọlọrun wepọ mọ.

28 Ni ṣiṣe iṣẹ lori ẹri ti Jehofah Oluwa Ọba Alaṣẹ fifun wa, awa yio yẹra fun didi ọmọlẹhin eke Messiah ti njanikulẹ. Kakabẹ, awa yio ní iriri ayọ mimọ Messiah totọ na lati ọdọ Ọlọrun ati titẹle ẹni na nipasẹ ẹniti gbogbo orilẹ-ede aiye yio ri ibukun aiyeraiye gbà.

[Ibeere]