Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Yiya “Ọjọ” Iṣẹda Keje Si Mimọ

Yiya “Ọjọ” Iṣẹda Keje Si Mimọ

Ori 15

Yiya “Ọjọ” Iṣẹda Keje Si Mimọ

1, 2. (a) Pẹlu fifọ ori Ejo Nla na, “ete aiyeraiye” Ọlọrun yio ha ti de imuṣẹ rẹ̀ ni kikun bi? (b) Tani o jẹ ete Ọlọrun fun lati jẹ anfani lati inu fifọ ori Ejo na?

FUN ire ainipẹkun araiye, iṣẹgun ete aiyeraiye Ọlọrun ninu Kristi Jesu Oluwa wa,” ti a ti nreti tipẹtipẹ ti sunmọle girigiri. Eyiyi ki ha iṣe ohun ti a le waláyò fun, ohun kan lati ri ki a si jẹ anfani ninu rẹ̀ pẹlu ayọ aiṣefẹnusọ? Iyoku Israeli ti ẹmi ti o là a já ati “ogunlọgọ nla” ti ẹgbẹ awọn ẹlẹri Jehofah yio ri iru iṣẹgun bẹ ki nwọn si jẹ anfani lati inu rẹ̀ titilai fábàdà. Ṣugbọn “ete aiyeraiye” Ọlọrun niti “iru-ọmọ” na ti “obirin” Rẹ̀ li ọrun koiti ni ṣe aṣeyọri rẹ̀ ni kikun nigbana. O nilati ma ba a lọ siwaju si awọn iṣẹgun miran nigba ati titi de opin ẹgbẹrun ọdun ti a yan fun iṣakoso Messiah na Jesu ati 144,000 mẹmba ẹlẹgbẹ “iru-ọmọ Abrahamu” na. (Ifihan 20:4-6; Galatia 3:8, 16, 29) Bawo ni?

2 O dara, o jẹ “ete aiyeraiye” Ọlọrun pe araiye, ti a ti bí sinu ẹṣẹ ati iku, nilati jẹ anfani nipa fifọ́ ori Ejo Nla na. Gẹgẹ bi ileri Ọlọrun fun Abrahamu, gbogbo idile aiye ati gbogbo orilẹ-ede nilati bukun fun ara wọn, ki nwọn ri ibukun ainipẹkun gba, nipasẹ “iru-ọmọ” Abrahamu ti ẹmi. (Genesisi 12:3; 22:18) Ẹgbẹ̀run ọdun iṣakoso Kristi yio fi akoko silẹ fun iru iṣẹ ibukun bẹ.

3. Fun imuṣẹ ete Ọlọrun akọkọ wo ni ẹgbẹrun ọdun iṣakoso lori ilẹ aiye fi nilati wà, ati nipa tani?

3 Jesu Messiah na ati 144,000 ajumọ-jọba pẹlu rẹ̀ ti a ṣelogo ati alufa ọmọ abẹ yio ní lọkan ete Ọlọrun Ẹlẹda ni akọkọ bẹrẹ ni fifi enia si ori ilẹ aiye ninu Ọgba Edeni. Eyini ni lati mu ki gbogbo ilẹ aiye dara gẹgẹbi Ọgba Edẹni agbaiye kan. O jẹ ete Ọlọrun akọkọ ti a ko le yipada lati mu ki ilẹ aiye Paradise yi kun fun awọn ọkunrin ati obirin olododò ati pipe, ki awọn wọnyì ma gbe ihinyi titilai ninu ibalo alalafia ati ifẹ pẹlu Baba wọn ọrun gẹgẹ bi mẹmba idile agbaiye rẹ̀ ti ọrun ati ti aiye, awọn mẹmba eto agbaiye Rẹ̀. Gbogbo ẹja okun ati ẹiyẹ oju ọrun ati gbogbo ẹda aláyè ti nrako lori ilẹ, ti ọsin ati igbo, yio wà ni itẹriba alailewu, alaipanilara si iran enia oniwa-bi-Ọlọrun yi. (Genesisi 1:26-31; Isaiah 45:18; Orin Dafidi 115:16; 104:5) Fun imuṣẹ eyi, ete Ọlọrun akọkọbẹrẹ, “iru-ọmọ” “obirin” Ọlọrun li ọrun nilati jọba fun ẹgbẹrun ọdun. Iṣẹ mimu eyi ṣẹ li a yan fun Jesu Messiah, ẹniti, nigbati o wà li aiye, a npe ni “Ọmọ enia.”—Orin Dafidi 8:4-8; Heberu 2:5-9.

4. Eṣe, lẹhin iṣelogo iyoku Israeli tì ẹmi, ti a ko fi ni fi “ogunlọgọ nla” ti o la a ja na silẹ li awọn nikan gẹgẹ bi awọn enia olugbe ilẹ aiye?

4 Nitorina, lẹhinti iyoku ti ẹmi na ti o là a já ba pari ọna igbesi aiye wọn lori ilẹ aiye ti a si ṣe wọn logo pẹlu Jesu Messiah ti njọba ati gbogbo awọn ajumọjogun rẹ̀ miran, “ogunlọgọ nla” miran ti o la “ipọnju nla” na ja li a ko ni fi silẹ ki awọn nikan ma gbe aiye ti a fẹ̀ mẹ na. Nwọn ti kere ju ni iye lati “kún ilẹ aiye.” Siwaju si i, ki iṣe awọn nikan li a fi ẹbọ enia pipe Jesu Ksristi Oluwa rà pada; a pa a ni “gigisẹ” ki o ba le “tọ́ iku wo fun olukuluku enia”; o “fi ara rẹ̀ ṣe irapada fun gbogbo enia.” (Heberu 2: 9:1 Timoteu 2:5, 6) Ọpọ awọn wọnni ti a ti ra pada li o ti ku nisisiyi ninu iboji gbogbo araiye. Bawo li a ṣe le ran Wọn lọwọ lati jẹ anfani lati inu irapada Messiah? Nipa ajinde oku ti a ṣeleri. (Jobu 14:13, 14; Isaiah 26:19; Matteu 22:31, 32; Johannu 5:28, 29; Iṣe 24:15; Ifihan 20:12-14) Nipa bayi “ogunlọgọ nla” na ti o là a já ni arádọta ọkẹ awọn wọnni ti a jí dide yio darapọ mọ, gbogbo wọn jẹ atọmọdọmọ tọkọtaya akọkọ na, Adamu ati Efa. Wo iṣọkan idile agbaiye lẹkansi i!

5. (a) Ete Ọlọrun miran wo li o wà nibẹ fun Kristi ati 144,000 lati muṣẹ? (b) Bawo ni Ọlọrun ṣe tẹsiwaju lati simi ni “ọjọ” iṣẹda keje rẹ̀?

5 Ete pataki kan mbẹ nisisiyi ti Jesu Kristi ti njọba ati 144,000 awọn ajumọ-jọba pẹlu rẹ̀ yio muṣẹ. Kini eyi? Sisọ “ọjọ” keje iṣẹda Ọlọrun di onibukun, ọjọ mimọ kan. Lẹhin ti Ọlọrun dá Adamu ati Efa ti o si fun wọn ni aṣẹ iṣẹ wọn, ti o fi lelẹ niwaju wọn ete Wọn ni igbesi aiye ninu Paradise, “ọjọ” iṣẹda kẹfa Ọlọrun pari, “ọjọ” iṣẹda keje si bẹrẹ, ni nkan bi ẹgbáta ọdun sẹhin. O ya “ọjọ” iṣẹda yi si mimọ gẹgẹbi “ọjọ” Isimi kan fun ara Rẹ̀. Ninu rẹ̀ on yio ṣiwọ kuro ninu iṣẹ iṣẹda lori ilẹ aiye, ti o nsimi kuro ninu iru iṣẹ bẹ, ki iṣe nitori rẹ̀, ṣugbọn lati jẹki tọkọtaya ekini ati awọn atọmọdọmọ wọn sìn I gẹgẹ bi Ọlọrun wọn aláyé ati otitọ nipa jijọsin fun u, ti nwọn nṣe iṣẹ ti on ti yan fun wọn. O mọ pe ete rẹ̀ ti a ti kede fun wọn li a le muṣẹ nigba ẹdẹgbaárin ọdun ti o tẹle e, “ọjọ” Isimi Rẹ̀.

“Ọlọrun si busi ọjọ keje, o si yà a si mimọ; nitori pe, ninu rẹ̀ li o simi kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo ti o ti bẹrẹ si iṣe.”—Genesisi 2:3.

6. (a) Bawo ni a ṣe ba “ọjọ” iṣẹda keje Ọlọrun jẹ gẹgẹ bi ọjọ Isimi Rẹ̀? (b) Sibẹsibẹ, bawo ni Ọlọrun yio ṣe sọ ọ di “ọjọ” onibukun ati mimọ?

6 Ko pẹ ko jinna lẹhinna ọmọ Ọlọrun ti ẹmi na ti o sọ araa rẹ̀ di Satani Eṣu bẹrẹsì bà “ọjọ” keje iṣẹda mimọ ti Jehofah Ọlọrun jẹ́. Fun ẹgbáta ọdun ni on ati “iru-ọmọ” rẹ̀ ti ri aye lati tẹsiwaju ninu isapa wọn lati mu ki o dabi ẹnipe o jẹ “ọjọ” kan ti a gegun fun, alaimọ, ti nyọ “isimi” Ọlọrun lẹnu, lati gbiyanju lati mu ki o lodi si “ọjọ” Isimi rẹ̀ ti on ti ya si mimọ. Ṣugbọn lasan ni! Ni ẹgbẹrun ọdun na ti a ti sọ Ejo Nla na ati “iru-ọmọ” ẹmi eṣu rẹ̀ sinu ọgbun ainisalẹ, Jehofah Ọlọrun yio yí gbogbo iwa buburu pada eyiti awọn oluba-Isimi-Jehofah-jẹ lori ilẹ aiye ti ṣe. Nipasẹ iṣakoso Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi fun ẹgbẹrun ọdun, Jehofah Ọlọrun yio gbe iran enia ga soke, eyiti o wá lati ọdọ tọkọtaya akọkọ, sinu ijẹpipe enia ati alaìlẹgbẹ, ayafi awọn ọlọtẹ, alaigbọran ninu iran enia li ao parun gẹgẹ bi ẹniti ko bọwọ fun “ọjọ” Isimi nla ti iṣe ti Jehofah Ọlọrun. (Ifihan 20:14, 15) A o mu Paradise bọ si ilẹ aiye ao si mu ki o kari aiye. Gbogbo aiye yio kun fun iran enia lati ọdọ tọkọtaya akọkọ, ao si ti ṣe ikawọ gbogbo ilẹ aiye nigbana.—Genesisi 1:28.

7. Adura wo ti Jesu kọni ni yio tipa bayi ni imuṣẹ, bawo ni on

7 Nipa imuṣẹ “ete aiyeraiye Ọlọrun ti o ti pinnu ninu Kristi Jesu Oluwa wa,” “ọjọ” iṣẹda keje Ọlọrun yio pari pẹlu ibukun, itẹ-lọrun, iyasimimọ. Bibukun ti Jehofah ti bukun “ọjọ” na ni ẹgbáta ọdun sẹhin ti o si yà a si mimọ nigbana li a ko i yipada si ẹgan ete aiyeraiye Rẹ̀. Adura Messiah na, “Ki ijọba rẹ de. Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe li aiye, bi ti ọrun,” yio ni imuṣẹ ologo ni kikun. (Matteu 6:10) Nigbati o ba ti mu “ete aiyeraiye” Jehofah ṣẹ fun iṣẹgun ete na ti o mu ọla wa fun Ọlọrun, lẹhinna ni Jesu Kristi yio “fi ijọba fun Ọlọrun ani Baba,” nipa bayi ti o fi ara rẹ̀ sabẹ Jehofah Ọga Ogo Julọ, Ọba Alaṣẹ Agbaiye. (1 Korinti 15:24-28) Pẹlu iṣotitọ on yio da orukọ Jehofah ọba alaṣẹ agbaiye lare.

DIDA ARAIYE ONIGBỌRAN LARE SI IYE AIYERAIYE

8. Ipo wo ni araiye ti a mu padabọ sipo yio wà nigbana niwaju Ọlọrun, ati, ṣaju dida ẹnikẹni lare fun iye ainipẹkun, kini On yio ṣe

8 Araiye ti a ti mu padabọsipo duro li ẹsẹ wọn nisisiyi, gan gẹgẹ bi Adamu pipe ati Efa alaijẹbi ti ṣe wà ninu Paradise Ọgba Edeni nigbati Ọlọrun fun wọn ni iṣẹ isin mimọ wọn fun u. Ewo ninu araiye ti a mu padabọsipo ninu Paradise ilẹ aiye ni yio jẹ olôtọ si Jehofah gẹgẹ bi ọba alaṣẹ agbaiye ati Ọlọrun Ẹlẹda onifẹ, Orisun gbogbo iye? Tani on funrarẹ̀ yio dalare tabi kà si olododo si iye ainipẹkun ninu Paradise ilẹ aiye? Lati dán gbogbo araiye ti a ti mu padabọsipo wò lori koko pataki yi, Jehofah yio tẹwọgba ijọba ti Jesu Kristi da pada fun u yio si tú Ejo Nla na ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ silẹ kuro ninu ọgbun ainisalẹ. On yio jẹki awọn ẹda ẹmi ọlọtẹ ti a ko kọlẹkọ wọnyi gbiyanju lati dán araiye wò ki o si tan wọn jẹ lẹkansi i.

9. (a) Kini yio ṣẹlẹ si awọn enia ti a mu padabọ sipo ti o juwọ

9 Jehofah ko sẹ pe diẹ ninu araiye ti a ti mu pada bọsipo yio yọda ara wọn fun Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ lati tannijẹ, gẹgẹ bi Adamu pipe ati Efa ti ṣe ninu Ọgba Edeni. O fi aye silẹ fun awọn enia kan ti a ko mọ iye rẹ̀ lati ṣe bẹ. Nigba ti a ba ti fi aye silẹ fun idanwo na ni kikun ti o si ti pin araiye si ọtọtọ li aile-ṣe-yipada niti bi olukuluku ti ṣe duro niti ọran jijẹ ọba alaṣẹ agbaiye ati jijẹ Ọlọrun, iparun yio wa lati ọrun sori awọn enia ọlọtẹ. Lakotan, o wa kàn olori oluba Isimi Jehofah jẹ na, Satani Eṣu, ati “iru-ọmọ” ẹmi eṣu rẹ̀ lati parun. Li aisi aniani “iru-ọmọ” “obirin” Ọlọrun li ọrun ni yio ṣe eyi, nitoripe a ti yan “iru-ọmọ!” na lati fọ́ “ori” Ejo na, gẹgẹ bi “ete aiyeraiye” Ọlọrun ti wi gẹgẹ bi a ti sọ ọ ni Ọgba Edeni. (Genesisi 3:15) Ko si pipada mọ fun Satani Eṣu ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ sinu ọgbun ainisalẹ, bikoṣe iparun yányán gẹgẹ bi ina ti o dapọ mọ imi-ọjọ ni yio jẹ ipin tiwọn. Ko si iwosan fun igba diẹ fun ipo ikẹhin yi, ti fifọ ori Ejo Nla na run patapata. Ko si awọn anfani miran ti a tun yọda fun u mọ lati huwa gẹgẹ bi Oludanwo.—Ifihan 20:7-10.

10. Bawo ni awọn wọnni ti o jẹ olóòótọ́ si Jehofah gẹgẹ bi ọba alaṣẹ ati jijẹ Ọlọrun rẹ̀ yio ṣe ri èrè gbà?

10 Wo iṣẹgun alade ti yio wa fun “ete aiyeraiye Ọlọrun ti o ti pinnu ninu Kristi Jesu Oluwa wa”! Awọn wọnni ninu araiye ti o fi ipinnu Wọn aileyipada han lati ṣiṣẹ-sin ati lati ṣe igbọran si Jehofah gẹgẹ bi Ọba Alaṣẹ Agbaiye ati Ọlọrun otitọ ati aláyẹ, ni On yio dalare gẹgẹ bi olododo. Lori awọn ti a dalare wọnyi ni on yio fi èrè ẹbun iye ainipẹkun fun ninu Paradise ilẹ aiye pipe na, apoti itisẹ Ọlọrun. (Isaiah 66:1) On yio fi ete ti ntẹnilọrun-titi, ti ndunmọni-titi kún igbesi aiye wọn ailopin, si ogo Rẹ̀ nipasẹ Kristi Rẹ̀, Jesu Oluwa wa. (Ifihan 21:1-5) Halleluyah!—Orin Dafidi 150:6.

11. Kini ohun rere ti o wà nibẹ fun wa lati ṣe niti ete Ọlọrun ti ko ni ifiwera?

11 Ãsiki kan ni yi fun araiye laisi ifiwera! O wà fun awọn wọnni ti o mu igbesi aiye wọn nisisiyi ba ’’ete aiyeraiye’’ Ọlọrun mu. Ko si ohun ti o tun le daraju sisọ ete Ọlọrun di ete wa.

[Ibeere]

yio si ṣe fihan nigbana jijẹwọ Jehofah gẹgẹ bi ọba alaṣẹ agbaiye?

silẹ fun itanjẹ Ejo na ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀? (b) Bawo li a ṣe mu ipo ikẹhin ninu “ete aiyeraiye” Ọlọrun ṣẹ?