lwaláyè Enia Lẹhin-ode Paradise Titi Di Igba Ikun-Omi
Ori 6
lwaláyè Enia Lẹhin-ode Paradise Titi Di Igba Ikun-Omi
1. Kini ami nipa ’’iru-ọmọ’’ ete rẹ̀ na ni Ọlọrun sọ di mimọ̀, eyi si gbe ibere wo dide?
BI ỌJỌ ti ngori ọjọ Olore enia li ọrun mu ki ami “ete aiyeraiye!” rẹ̀ di mimọ̀ eyiti o lu okùn ibakẹ-dun kan ninu ọkàn wa. On ni pe “iru ọmọ” “obirin”ọrun rẹ̀ ti a pete yio ní iwaláye kukuru lori ilẹ aiye lárin araiye. Lẹsẹkẹsẹ li eyiyi gbe ibere kan dide ninu ọkàn wa, niwọnbi o ti jẹ pe “iru-ọmọ” na li ao bí sinu iran enia wa, nigbana nipasẹ ila idile wo lati ọdọ Adamu ati Efa ni “iru-ọmọ” na yio gba de?
2. Si kiki kini Ọlọrun fi opin si awọn ohun ti o wa ninu Bibeli, esitiṣe ti a fi nilati kẹkọ Bibeli?
2 Itan ila idile enia ti “iru-ọmọ” na ni ohun pataki na fun wa lati mọ. Itan awọn enia ati orilẹ-ede ti ko ni ohun kan lati ṣe pẹlu ilana igbesi aiye “iru-ọmọ” yi ki iṣe ohun iyẹsilẹ pe ko ṣe pataki tabi niyelori. Idi ni yi ti Jehofah Ọlọrun fi fi awọn ohun ti o wà ninu Bibeli Mimọ mọ si kiki sisọ fun wa nipa iṣiṣẹ ila idile “iru-ọmọ” yi. Nipa nini ti a ni imọ itan Bibeli yi yio le ṣéṣe fun wa lati mọ ẹniti “iru-ọmọ” na ti yio fọ ori Ejo yi iṣe, awa ki yio si fi ara wa silẹ lasan fun itanjẹ ki a si ṣì wa lọna nipasẹ atannijẹ kan, iru-ọmọ eke kan. Itanjẹ le yọrisi iparun aiyeraiye fun wa Atannijẹ Nla na, ẹniti o gbe eke ti ntannijẹ kalẹ ninu ọgba Edeni ti o si jẹ ọta “iru-ọmọ” toôtọ na, ṣì wà pẹlu awọn ọgbọn ẹtan rẹ̀ ti o ti lọjọ lori. On yio fẹ lati tan gbogbo wa jẹ kuro lọdọ “iru-ọmọ” ’’ete aiyeraiye“ Ọlọrun. Nitorina awa nilati kẹkọ Bibeli.
3. Tani ọmọkunrin akọbi Adamu, nitorina ibere wo ni a gbe dide nipa Seti ọmọ Adamu?
1 Kronika 1:1-4) Seti ki iṣe akọbi ọmọ Adamu lẹhin-ode Paradise Igbadun. Kaini ni, Abeli li a si tun darukọ gẹgẹ bi ọmọ Adamu ati Efa. (Genesisi 4:1-5) Eṣe, nigbana, ti Seti fi jẹ ẹnikan ti a kọ orukọ rẹ̀ sinu ila idile na titi de ọdọ Noa?
3 Ninu Bibeli Heberu, awọn iwe Kronika meji li a kọ silẹ kẹhin, ki si iṣe iwe asọtẹlẹ Malaki. Nisisiyi, bi a ba yiju si iwe ekini Kronika awa ṣakiyesi pe o bẹrẹ pẹlu ila iran mẹwa lẹhin Adamu, bayi: ”Adamu, (1) Seti, (12) Enoṣi, (3) Kenani, (4) Mahaleli, (5) Jaredi, (6) Enoku, (7) Metuselah, (8) Lameki, (9) Noa, (10) Ṣemu, Hamu ati Jafeti.’’ (4. Kini fihan pe Ọlọrun ko wewe pe ki Seti jẹ ekini ti a kọkọ darukọ rẹ̀ ninu ila idile lati ọdọ Adamu?
4 Jehofah Ọlọrun ha wewe rẹ̀ lọná bẹ bi? Bẹkọ, nitoripe eyini yio tumọsi pe Ọlọrun wewe pe ki Kaini pa Abeli aburo rẹ̀ ọkunrin ki o si tipa bayi ṣaika ara rẹ̀ yẹ kuro ninu jijẹ ẹni na nipasẹ ẹniti araiye loni yio tọsẹ ila idile rẹ̀. Bẹni Ọlọrun ko wewe pe, nipasẹ ipania buburu, a nilati ké Abeli kuro laipe ọjọ ki o to ni ọmọ ti a nfẹ ati pe nipa bayi a nilati fi Seti rọpo rẹ̀. (Genesisi 4:25) Pe Ọlọrun ko wewe pipa Abeli ki o ba le fi aye silẹ fun Seti ṣe kedere lati inu ikilọ ti Ọlọrun fifun Kaini ki o má ba ṣubu sinu ẹṣẹ paraku nitori bibinu pe Ọlọrun ko tẹwọgba ẹbọ rẹ̀ ṣugbọn a tẹwọgba ẹbọ Abeli arakunrin rẹ̀.—Genesisi 4:6, 7.
5, 6. Bibi ti abi Seti ni aworan ati jijọ Adamu tumọsi kini fun u, bawo si ni sisọ ti o sọ orukọ ọmọ rẹ̀ ni Enọṣi ṣe fi imuṣẹ otitọ yi han?
5 Bẹkọ, Jehofah Ọlọrun ko wewe rẹ̀ lọna bẹ, ṣugbọn o gba akoko gigun ki a to bi ọmọ Adamu kan nipasẹ ẹniti ila idile na yio nasẹ titi de bibi “iru-ọmọ” na, Messiah, ninu ara. Fifalẹ ninu bibẹrẹ ila idile ti a ṣe ojurere si yi lati ọdọ Adamu li a fihan ninu Genesisi 5:3, nibiti a ti kà pe: “Adamu si wà li adoje ọdun, o si bi ọmọkunrin kan ni jijọ ati li aworan ara rẹ̀; o si pe orukọ rẹ̀ ni Seti.” Ni jijọ ati ni wiwa li aworan Adamu, tabi, ni jijẹ iru Adamu, Seti jẹ alaipe, o si ti jogun ẹṣẹ o si tipa bayi wà labẹ idalẹbi iku. Imuṣẹ otitọ yi dabi ohun ti a fihan ninu orukọ na ti Seti fifun ọmọ rẹ̀, nipa ẹniti a ka pe: “Ati Seti, on pẹlu li a bi ọmọkunrin kan fun; o si pe orukọ rẹ̀ ni Enoṣi.” (Genesisi 4:26) Orukọ na ní ero “alaisan, alailera, ti a ko le wosan” ninu.
6 Ni ibamu pẹlu eyi, ọrọ Heberu na e-osh, nigbati a ko ba lò o gẹgẹbi orukọ gidi, li a tumọsi gẹgẹbi “enia kiku.” Fun apẹrẹ, nigbati Jobu ti a pọnloju rekọja álà na wipe: “Kili enia [kiku] [Heberu:e.nosh’] ti iwọ o má kokiki rẹ̀? ati ti iwọ iba fi gbe ọkàn rẹ le e?”—Wo Jobu 7:17; 15:14; pẹlu, Orin Dafidi 8:4; 55:13; 144:3; Isaiah 8:1.
7-9. (a) Aṣa isin wo ni a bẹrẹ rẹ̀ ni awọn ọjọ Enoṣi? (b) Kini fihan boya aṣa yi ṣanfani fun enia tabí bẹkọ?
7 Igbesi aiye Enoṣi atọmọdọmọ Adamu li ohun Pataki kan samisi, eyiti Genesisi 4:26 pe afiyesi wa si, ti o wi pẹlu itọkasi si bibi Enoṣi fun Seti pe: “Li akoko na li awọn enia bẹrẹ si ikepe orukọ[Jehofah]. A bi Enoṣi nigbati Seti wà li ọmọ ọdun marundinladọfa, eyiti yio tumọsi ojilerugba ọdun o din marun ọdun lẹhin dida Adamu. (Genesisi 5:6, 7) Li akoko na iye enia lori ilẹ aiye ti pọ si i nipasẹ igbeyawo ọpọ awọn ọmọkunrin ati ọmọbirin Adamu laárin ara wọn ati nipasẹ awọn igbeyawo lárin awọn atọmọdọmọ wọn. Bibẹrẹ lati pe orukọ Jehofah lárin awọn enia ti npọ si i yi ha jẹ ohun kan ti o ṣanfani fun iran enia ti o si bọwọ fun Ọlọrun bi? O ha jẹ ohun ti awọn ajihinrere ode oni yio pe ni ”isin isọji kan bi? Septuagint Version ti Greek igbánì, ti awọn Ju ti ngbe Alekandria, Egipti, ṣe, tumọ ọrọ Heberu yi pe: “Seti si bi ọmọ kan, o si pe orukọ rẹ̀ ni Enoṣi: o ni ireti lati ke pe orukọ Oluwa Ọlọrun.”—Genesisi 4:26, LXX, itẹjade ti Bagster and Sons Limited.
8 Itumọ Jerusalem, Bible mu ero kanna jade, nigbati o wipe: ’’Ọkunrin yi li ẹni ekini lati pe orukọ Yahweh.“ Ṣugbọn iru itumọ bẹ mu kuro ninu ironu ijọsin ti a tẹwọgba eyiti Abeli olôtọ ṣe fun Jehofah ṣaju ki Kaini ojowu to pa a. Niti The New English Bible o kà pe: ”Li akoko na awọn enia si bẹrẹsi pe orukọ OLUWA.“ Genesis 4:26 pe: ”Nigbana li a fi ibajẹ pe Orukọ Oluwa.“ Eyini ni pe, awọn enia ati àwọn nkan alailẹmi ti fi awọn animọ Jehofah fun ar wọn a si npe wọn bẹ gẹgẹ. Eyiyi yio tumọsi pe ibọriṣa li orukọ Jehofah bẹrẹ nigbana.
(Ati pẹlu, The New American Bible) Ṣugbọn,Targum Palestine igbánì ní ero ti ko dara nipa ọran na. Rashi olokiki na(Rabbi Shelemoth Yitschaki, 1040-1105 C.E tumọ9 Pe pipe orukọ Jehofah ko mu ironu sisunmọ Ọlọrun dani li a fihan ninu otitọ na afi igbati o di irinwo ọdun o dín mẹtala lẹhin bibi Enoṣi li a bi ọkunrin kan ti o tẹwọgba jijẹwọ Ọlọrun. On na ni Enoku.
BIBA ỌLỌRUN RIN LẸHIN-ODE PARADISE
10. Sisọ ti a sọ pe Enoku ba Ọlọrun otitọ rin tanmọlẹ lọna wo lori Jaredi baba rẹ̀ ti o gbé li aiye ju u lọ?
10 Nipa ọmọ-ọmọ-ọmọ ọmọ Enoṣi yi, ẹniti a bi ni 3404 B.C.E. (tabi 622 A.M.), a kọwe pe:Enoku si wà li ọgọta ọdun o le marun, o si biMetusela. Enoku si ba Ọlọrun (otitọ) rin li ọdunrun ọdun lẹyin ti o Metusela, o si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin. Gbogbo ọjọ Enoku si jẹ irinwo ọdun o di marundinlogoji’’(Genesisi 5:21-23) Eyiyi jẹ igbesi aiye kukuru fun Enọku ni ifiwera, ẹniti baba rẹ̀ Jaredi gbe aye fun ẹgbẹrun ọdun o din mejilelogoji ati ẹniti ọmọ Metuselah gbe aiye fun ẹgbẹrun ọdun o din mọkanlelọgbọn lati di ọkunrin ti o darugbo julọ ninu akọsilẹ. Sibẹ Enọku si ‘’mba Ọlọrun otitọ rin’’ A ko wi eyi nipa baba rẹ̀ Jaredi, ẹniti o gbé aiye ni ẹgbẹrin ọdun lẹhin ti obi Enoku. (Genesisi 5:18, 19) O ṣe kedere, nigbana, pe igbagbọ Jaredi ko dabi igbagbọ Enọku ninu Ọlọrun on ko si rin ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun tabi ete kan ti a kede.
11 A rohin rẹ̀ pẹlu idaniloju pe Enoku jẹ woli Ọlọrun otitọ. Ninu lẹta kan ti a kọ ninu ọgọrun ọdun ekini C.E. a kọ ọ pe: ”Awọn wọnyi pẹlu ni Enoku, ẹni keje lati ọdọ Adamu, sọtẹlẹ fun, wipe Kiyesi i, (Jehofah) mbẹ pẹlu ẹgbẹgbarun awọn enia rẹ̀ mimọ. Juda 14, 15) Asọtẹlẹ yi laisi aniani ní iṣe pẹlu ipo isin ti mbẹ nigbana lọhun ni ọjọ aiye Enoku. Bi ko ba ṣe bẹ, kini yio jẹ ipilẹ fun fifunni ni iru asọtẹlẹ onimisi bẹ eyiti o kilọ nipa idajọ Jehofah lori gbogbo awọn alaiwa bi-Ọlọrun eyiti o daju bi igbati o ti ṣẹlẹ gan? Nitoripe Enoku ki iṣe ọ̀kan ninu awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ni ọjọ aiye rẹ̀, Ọlọrun le lò o gẹgẹbi agbọrọsọ fun asọtẹlẹ na. Biotilẹjẹpe o ngbe lẹhin ode Paradise ti awọn kerubu nṣọ eyiti o ṣì wa sibẹ nigba aiye Enoku, on mba “Ọlọrun otitọ rin.’’
Lati ṣe idajọ gbogbo enia, lati dá gbogbo awọn alaiwa-bi-Ọlọrun lẹbi niti gbogbo iṣẹ aiwa-bi-Ọlọrun wọn, ti nwọn ti fi aiwa-bi-Ọlọrun ṣe, ati niti gbogbo ọrọ lile ti awọn ẹlẹṣẹ alaiwa-bi-Ọlọrun ti sọ si i.? (12, 13. Gẹgẹbi ero awọn Ju ti ri, ati ti Kristendom, nibo li a gbe Enoku lọ?
12 Eṣe, nigbana, ti Enoku fi gbe aiye li ọjọ kukuru tobẹ ni ifiwera pẹlu awọn akoko wọnni? Genesisi 5:24 sọ fun wa: ”Enoku si ba Ọlọrun (otitọ) rin: on ko si si; nitori ti Ọlọrun mú u lọ.“
13 O le ṣéṣe pe Enoku wà ninu iru ipo ailayọ paraku kan nigbati Ọlọrun mu u lọ. Ihaṣe pe awọn ọta Enoku halẹ lati gba ẹmi rẹ̀ bi, nitorina ki Ọlọrun si mu u kuro ki o si pa a mọ nitori iku ojiji? Awa ko mọ? Ibere na dide pe, Nibo li Ọlọrun mu u lọ? Ero awọn Ju kan ni pe Ọlọrun mu u lọ si ọrun. Eyini tilẹ jẹ ero Kristendom loni. Fun apẹrẹ, ninu lẹta kan ti a kọ si awọn Heberu ni ọgọrun ọdun ekini C.E., alaye kan li a ṣe lori Enoku eyiyi si li ọna ti A New Translation of The Bible, lati ọwọ Dr. James Moffatt, ti ọgọrun ọdun yi, ṣe tumọ Heberu 11:5, bayi: ”Nipa igbagbọ li a gbe Enoku re ọrun, nitori ki o má ba ku (iku ko li agbara lori rẹ̀, nitoripe Ọlọrun ti muu, u lọ.) “The New English Bible kà nihin bayi: ”Nipa igbagbọ li a gbe Enoku lọ si igbesi aiye miran lairi iku; a ko ri-i nitoripe Ọlọrun ti mu u lọ. Nitoripe o jẹ ẹri Iwe Mimọ pe ki a to mu u lọ o wù Ọlọrun.“—Wo The Jerusalem, Bible pẹlu.
14. Kini fihan boya ’ririn pẹlu Ọlọrun ka Enoku yẹ lati lọ si ọrun?
Orin Dafidi 89:48 bere ibere na: ’’Ọkunrin wo li o wà láyè, ti ki yio ri iku Ti yio gba ọkàn rẹ̀ lọwọ isa oku?” Bẹ gẹgẹ, pẹlu, Enoku ti ri gba lati ọwọ Adamu ẹlẹṣẹ ijogunba iku, on pẹlu si nilati ku, laibikita fun ririn ti o ba Ọlọrun otitọ rin. A tun kọwe lẹhinna nipa ọmọ-ọmọ ọmọ Enoku pe eyiyi pẹlu “ba Ọlọrun otitọ rin”; sibẹ ẹniti a sọrọ rẹ̀ kẹhin yi li a ko ké igbesi aiye rẹ̀ kuru. On gbe li aiye ju Adamu lọ—fun ẹgbẹrun ọdun o din adọta, adọta le ni ọgọrun ọdun mẹsan. (Genesisi 6:9; 9:28, 29) Nitorina, rirìn ti Enoku ba Ọlọrun rìn fun akoko ti o din si ti awọn atọmọdọmọ rẹ̀ ko fun u ni aṣẹ lati lọ si ọrun tabi lọ si igbesi aiye miran ju bi ririn ti Noa ba Ọlọrun rin fun igba pipẹ bẹ ko ti fun u ni iriri bẹ.
14 Sugbọn,15. Bawo, nigbana, li a ṣe le ṣí Enoku nipo pada ki o má ba ri iku?
15 Woli Mose kú ni ọgọfa ọdun Ọlọrun si sin i, nitorina loni ko si ẹnikan ti o mọ̀ titi di oni yi ibiti a sin Mose si. (Deuteronomi 34:5-7) Nitorina lojiji ni Ọlọrun mu Enoku kuro ninu iran awọn ẹlẹgbẹ rẹ̀, ibiti Enoku si ku si li a ko mọ̀, tabi iboji kankan. On ko ku iku ojiji lati ọwọ awọn ọta rẹ̀. On, nitoripe o jẹ woli, o le jẹ pe nigbati o wà ninu iran o ri iran eto awọn nkan titun Ọlọrun ninu eyiti Ọlọrun “yio gbé iku mì lailai.? (Isaiah 25:8) Ninu eto titun na Enoku reti lati wà ninu Paradise ori ilẹ aiye. Nigbati Enoku wà labẹ agbara iru iran bẹ nibiti itura yio ti de ba araiye kuro lọwọ iku nipasẹ ipese alánu Ọlọrun, Ọlọrun le ti mu u kuro ninu iran ki o si mu iwaláyẹ rẹ̀ isisiyi kuro, ki Enoku má ba le ni imọlara iku. Ni iru ọna agbayanu bẹ ohun ti a kọ sinu Heberu 11:5 yio ni imuṣẹ.
“Nipa igbagbọ li a ṣi Enoku nipo pada ki o má ba ri iku, a ko si ri i nibikankan nitoripe Ọlọrun ti ṣí i nipo pada; nitoripe ṣaju iṣipo-pada rẹ̀ a jẹri rẹ̀ pe o wù Ọlọrun.”—New World Translation, of the Holy Scriptures.
AWỌN ỌJỌ ṢAJU IKUN-OMI NA
16. Bawo li a ṣe mọ pe Adamu ati Metusela mọ ara wọn?
16 Metusela ọmọ Enoku li a bi ni 969 ọdun ṣaju ikun-omi agbaiye, nitorina o ku li ọdun Ikun-omi na. Biotilẹjẹpe Metusela jẹ ẹni kẹjọ ninu ila lati ọdọ Adamu wá, on ha mọ̀ Adamu obi rẹ̀ enia akọkọ bi? Bẹni. A da Adamu ni 1656 ọdun ṣaju Ikun-omi. On gbe li aiye ni 930 ọdun. Bi a ba ro ọdun aiye rẹ̀ mọ ti Metusela, o jẹ 1899 ọdun. Nipa yiyọ 1656 kuro ninu aropọ na, iyoku jẹ 243 ọdun. Nitorina awọn ọdun igbesi aiye Adamu ati Metusela wọ ara wọn fun 243 ọdun.—Genesisi 5:5, 21, 25-27.
17. Asọtẹlẹ wo ni Lameki, ọmọ Metusela, sọ nigba bibi Noa, esitiṣe ti orukọ yi fi ṣe dedé?
17 Metusela gbe li aiye to lati gbọ nipa ikilọ ti a kede nipa ikun-omi agbaiye ti mbọ, o si fẹrẹ ri ipari awọn imurasilẹ ti a ṣe fun iran enia diẹ lati la jamba agbaiye na ja. O ṣéṣe fun u lati ri atọmọdọmọ rẹ̀ Noa oniwasu ododo ti o nmurasilẹ fun enia lati la a ja. Ninu gbogbo awọn ọmọ Metusela, Lameki li ẹni na ti o di baba fun Noa. Ni akoko bibi Noa ni a misi Lameki lati sọ asọtẹlẹ kan nipa rẹ̀. Eyini fihan pe Ọlọrun pete lati lo Noa ọmọ Lameki. Lori eyi a kà pe: ”Lameki si wà li ọgọsan ọdun o le meji, o si bi ọmọkunrin kan: O si sọ orukọ rẹ̀ ni Noa, pe Eleyi ni yio tù wa ni inu ni iṣẹ ati lala ọwọ wa, nitori ilẹ ti (Jehofah) ti fibu.“ Lameki waláyé wọ̀ inu ọdun marun ṣáju Ikun-omi na. (Genesisi 5:27-31) Orukọ na Noa wà ni ibamu pẹlu asọtẹlẹ Lameki, nitoripe o tumọsi ”Isimi“ o si tumọsi itunu ninu isimi. Egún Ọlọrun li a nilati mu kuro lori ilẹ ti On ti gégun fun nitori irekọja Adamu.—Genesisi 3:17.
18. Nigbawo, ninu igbesi aiye Noa, ni ikun-omi na bẹrẹ, ti o si kasẹ lẹhinna?
18 Ikun-omi na de ninu ọgọrun ọdun kẹfa ninu igbesi aiye. (Genesisi 7:11; 8:13; 7:6) Jamba agbaiye ti o ṣẹlẹ li ọjọ Noa ṣapẹrẹ jamba agbaiye titobiju eyiti yio ṣẹlẹ laipẹ ninu iran tiwa, nitori idi eyi o yẹ fun ifọkansi wa.—Owe 22:3.
19. Bawo ni Noa ṣe dabi Enoku ninu ọna igbesi aiye rẹ̀?
Genesisi 5:32) Iru akọsilẹ wo ni Noa ṣe fun ara rẹ̀, ani ṣaju ki o to di baba? “Nwọnyi ni ìbí Noa: Noa ṣe olotọ ati ẹniti o pé li ọjọ aiye rẹ̀, Noa mba Ọlọrun otitọ rìn.” (Genesisi 6:9, 10) Nitorina Noa dabi Enoku.
19 Fun ọgọrọrun ọdun Noa, ti a bi ni 2970 C.E. (1056 A.M.), jẹ alailọmọ: ”Noa si jẹ ẹni ẹdẹgbẹta ọdun” Noa si bi Ṣemu, Hamu, ati Jafeti. (20. Eṣe ti ibere kan fi dide nipa “awọn ọmọ Ọlọrun otitọ” ti a rohin lori ilẹ aiye ni awọn ọjọ Noa?
20 Biotilẹjẹpe Noa jẹ atọmọdọmọ Seti ati Enoku ti o si “ba Ọlọrun otitọ rin,” sibẹ Noa li a ko pe ni ‘’ọmọ Ọlọrun otitọ.“ Bi a ko ba pe e bẹ, tani ẹlomiran lori ilẹ aiye ni awọn ọjọ wọnni ninu awọn ti o jade lati inu Adamu ẹlẹṣẹ ti a le tipa bayi pe bẹ? Tani, nigbana, li awọn wọnni ti a rohin pe o farahan lori ilẹ aiye ni awọn ọjọ Noa, awọn ẹniti a kà nipa wọn nisisiyi? ”O si ṣe nigbati enia bẹrẹ si rẹ̀ lori ilẹ, ti a si bi ọmọbirin fun wọn, ni awọn ọmọ Ọlọrun ri awọn ọmọbirin enia pe, nwọn lẹwa; nwọn fẹ aya fun ara wọn ninu gbogbo awọn ti nwọn yan. (Jehofah) si wipe, Ẹmi mi ki yio fi igba-gbogbo bá enia jà, ẹran-ara sa li on pẹlu: ọjọ rẹ̀ yio si jẹ ọgọfa ọdun.“ Genesisi 6:1-3.
21. Tani “awọn ọmọ Ọlọrun otitọ” wọnni, kini nwọn si ni ifẹ si lati ṣe?
21 Awọn ”ọmọ Ọlọrun“ wọnni ti nilati jẹ awọn angeli li ọrun, awọn ẹniti titi di akoko yi nwọn ti jẹ apakan eto Jehofah li ọrun ti ”awọn ọmọ Ọlọrun“ mimọ, ”obirin“ Jehofah li ọna apẹrẹ eyiti yio di iya fun ”iru-ọmọ“ ti a ṣeleri na. Nigba iṣẹda aiye fun ibugbe enia, nwọn ti ri iṣẹ iṣẹda Jehofah nwọn si ti kigbe iho ayọ. (Jobu 38:7; Genesisi 3:15) Ni riri igbeyawo ti a nṣe larin awọn enia, ni pataki eyiti o ṣẹlẹ larin awọn obirin ẹlẹwa, nwọn jẹki ifẹ fun igbesi aiye takọtabo wọ wọn lọkan pẹlu awọn obirin fun ara wọn.
22. Bawo ni ’’awọn ọmọ Ọlọrun otitọ” wọnni ṣe tẹ ifẹ wọn lọ́rùn ti nwọn si tipa bẹ dẹṣẹ?
22 Bawo ni awọn gẹgẹbi ẹda ẹmi ṣe le gbadun ibalopọ takọtabo pẹlu awọn obirin ẹlẹran ara lori ilẹ aiye? Lefitiku 18:22, 23) Ni kedere ”awọn ọmọ Ọlọrun“ wọnni ndẹṣẹ.
Nipa gbigbe awọ̀ ara enia wọ̀ gẹgẹbi awọn ọkunrin ẹlẹwa ati nipa mimu awọn enia lati fi ṣe aya ati nipa nini ibalopọ pẹlu wọn. Gẹgẹ bi Ẹlẹda ati Baba ọrun ti paṣẹ igbeyawo larin awọn ẹda enia ti o ni iṣẹda kanna ti ki si iṣe larin awọn ẹda ẹmi ati awọn ẹda enia, ”awọn ọmọ Ọlọrun“ wọnyi ko wá ki nwọn si gbe awọ enia wọ̀ gẹgẹ bi enia ẹlẹran ara ki nwọn ba le ṣiṣẹ gẹgẹ bi iranṣẹ fun Jehofah Ọlọrun, ti a palaṣẹ ki o si ran wọn. Nwọn tẹsiwaju lati mu idarudapọ ẹda jade—ẹmi ati enia, ti ọrun ati ti aiye. (23. Pẹlu iru ẹmi wo li Ọlọrun ti fi mba araiye ẹlẹṣẹ lo tipẹtipẹ, ṣugbọn kini on wá kede nisisiyi?
23 Nisisiyi o ju ẹgbẹrun ọdun lọ ti o ti kọja lati igba iṣọtẹ Adamu ni Edeni lodi si Jehofah Ọlọrun Ọba alaṣẹ. Jehofah ti huwa pẹlu ẹmi súrù ati ifarada si araiye ẹlẹṣẹ, nitoripe ani li ọjọ Enoku babanla Noa pápá, araiye ni gbogbogbo ti di ”alaiwa-bi-Ọlọrun“ paraku. Nisisiyi nwọn nwò inu iru ibajẹ titun kan ati iyipada ninu ibalo takọtabo nipasẹ igbeyawo larin awọn obirin ati awọn angeli ti o gbe awọ enia wọ. Akoko na yẹ ki o de nigbati Ẹlẹda onisúrù na nilati ṣiwọ lati ba araiye ti o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ lo pẹlu ẹmi ifarada ati ikora-ẹni-nijanu. Pẹlu ẹtọ kikun, Ọlọrun kede nikẹhin pe: ”Ẹmi mi ki yio fi igba gbogbo bá enia jà, ẹran-ara sa li on pẹlu: ọjọ rẹ̀ yio si jẹ ọgọfa ọdun.“—Genesisi 6:3.
24. (a) Nibẹ Ọlọrun ha ndiwọn ọjọ ori enia, bi o ti ri niti ọran Mose? (b) Kini ṣẹlẹ nigbana, esitiṣe ti akoko ọlọ́làwọ fi wa?
24 Eyini ki iṣe fifi ote le ori gigun ọjọ ori enia gẹgẹ bi o ti ri niti ọran woli Mose, ẹniti o gbe li aiye fun ọgọfa ọdun. O jẹ aṣẹ atọrunwa pe aiye iran enia alaiwa-bi-Ọlọrun yio ní kiki ọgọfa ọdun si i lati waláyè titi di igba ikun-omi. Nitorina aṣẹ atọrunwa yi li a tẹjade ni 1536 A.M. tabi 2490 B.C.E. Eyiyi tumọsi pe lọhun ”akoko opin” ti bẹrẹ fun aiye alaiwa-bi-Ọlọrun ni awọn ọjọ Noa. Ọlọrun ete nkà akoko awọn ohun ti nṣẹlẹ. Biotilẹjẹpe on ko wewe fun iru Genesisi 5:32; 7:11.
ohun iyalẹnu bẹ ti o ṣẹlẹ ninu ọran ’’awọn ọmọ Ọlọrun,” sibẹ on ní iṣakoko kikun na lọwọ on si le bojuto iṣẹlẹ ojiji na. On jẹ ọlọgbọn-gbogbo, alagbara-gbogbo. Fifi aye silẹ ti on fi aye silẹ fun igba akoko ti a mu gbérò ṣáju opin aiye alaiwa-bi-Ọlọrun na jẹ gbigba ti ẹnikan rò gán. Eṣe? Nitoripe aṣẹ atọrunwa na li a pa ni ogun ọdun ṣaju ki Noa to di baba sibẹ o fi akokosilẹ fun u lati bi ọmọ mẹta ati fun awọn wọnyi lati dagba di gende ki nwọn si gbeyawo ki nwọn si darapọ mọ baba wọn ni ṣiṣe imurasilẹ ti o yẹ fun lila ikun omi ti o banilẹru na já.—AWỌN NEFILIMU
25, 26. Kini a npe awọn ọmọ ti igbeyawo larin awọn angeli ati awọn obirin mu jade, esitiṣe?
25 Ọjọ aiye igbeyawo larin ’’awọn ọmọ Ọlọrun” ati awọn ọmọbirin onifẹ gbigbona kù si dẹdẹ. Ṣugbọn ọmọ bibi ha ṣeṣe lati inu idarudapọ awọn ẹda yi larin awọn ẹmi ti o gbe ara enia wọ̀ ati awọn ẹda obirin ẹlẹran ara pẹlu awọn agbara ibimọ? Genesisi 6:4 fun wa ni awọn otitọ ni idahun:
“Awọn òmìrán (Nefilimu) wà li aiye li ọjọ wọnni; ati lẹhin eyini pẹlu, nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wọle tọ̀ awọn ọmọbirin enia lọ, ti nwọn si bi ọmọ fun wọn, awọn na li o di akọni ti o wà nigbana, awọn ọkunrin olokiki.”
26 Awọn ọmọ ti o jade lati inu awọn igbeyawo ti o darupọ wọnyi jẹ awọn ọmọ ti obi wọn yatọ si awọn ọmọ enia a si npe wọn ni Nefilimu tabi Òmìrán. Orukọ yi tumọsi “Akenilulẹ,” lati fihan pe awọn ọmọ adamọdi alagbara wọnyi ti obi wọn yatọ si ara wọn nfi tipatipa gbe awọn ẹlomiran ṣubu tabi mu ki awọn enia alailagbara ṣubu. O gba akoko gigun lati loyun awọn Nefilimu wọnyi ati lati bí wọn ki nwọn si dagba di gende nigbana ati lati má ba igbesi aiye oniwa ipa wọn niṣo. Nitoripe nwọn jẹ awọn ọmọ adamọdi ti obi wọn yatọ si ara wọn, bi o ti tọ́ nwọn ko ni le mu iru wọn ti o jẹ ọkanna jade.
Genesisi 6:5-8) Inu Jehofah bajẹ pe enia ti On dá ti di alainilári tobẹ niti iwarere ati ti ẹmi. O jẹ ibanujẹ lati ni iru awọn enia oniwa ibajẹ bẹ lori ilẹ aiye. Awọn wọnyi li awọn ẹniti On pete lati wẹmọ kuro lori ilẹ aiye, ṣugbọn ki iṣe iran enia eyiti Noa olododo jẹ mẹmba rẹ̀.
27Idile enia ko ni anfani kankan nipa didarapọ timọ-timọ mọ “awọn ọmọ Ọlọrun” alaigbọran ti o gbe awọ enia wọ. “Ọlọrun si ri i pe iwa buburu enia di pipọ ni aiye, ati pe gbogbo ìrò ọkàn rẹ̀ kiki ibi ni lojôjumọ. Inu [Jehofah] si bajẹ nitori ti o dá enia si aiye, o si dùn u de ọkàn rẹ̀. (Jehofah) si wipe, Emi o pa enia ti mo ti da run kuro li ori ilẹ; ati enia, atiẹranko, ati ohun ti nrako, ati ẹiyẹ oju ọrun; nitori inu mi bajẹ ti mo ti dá wọn. Ṣugbọn Noa ri oju rere loju (Jehofah).” (28. Eṣe ti awa loni le fi dupẹ pe Ọlọrun pete lati fi opin si ipo iwa agbara ti mbẹ ṣaju Ikun-omi lori ilẹ aiye?
28 Ninu iyatọ gedegbe si Noa ati idile rẹ̀, “aiye si bajẹ niwaju Ọlọrun, aiye si kún fun iwa-agbara. Ọlọrun si bojuwo aiye, si kiyesi i, o bajẹ; nitori olukuluku enia ti ba iwa rẹ̀ jẹ li aiye.” (Genesisi 6:11, 12) Li awọn ọjọ wọnni ṣaju Ikun-omi aiye araiye ti wọ inu sanmani iwa-agbara. Loni aiye ti wọ inu “sanmani iwa-agbara” gẹgẹbi awọn alakiyesi ti ṣe pè e, lati igba ọdun na 1914 C.E., ọdun na ninu eyiti Ogun Agbaiye Kini bẹ silẹ pẹlu gbogbo iwa-agbara rẹ̀. Nitorina a le bere daradara pe, Bawo ni ipo aiye yio ti ri loni bi Ọlọrun Olodumare ba ti fi aye silẹ fun ‘’sanmani iwa-agbara” ṣaju Ikun-omi na lati ma ba a lọ laisi idaduro kankan? O mu ki a gbọnriri lati ronu nipa awọn ohun ti o le ṣẹlẹ. Tipẹtipẹ ṣaju akoko yi aiye iba ti di ibikan ti o lewu julọ lati gbe. Awa le dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o pete lati dá “sanmani iwa-agbara’’ na ṣaju Ikun-omi duro.
AIYE KAN DOPIN, IRAN KAN LA A JÁ
29. Awọn itọni Jehofah fun Noa ṣe dede pẹlu ete Ọlọrun wo fun ilẹ aiye?
29 Jehofah Ọlọrun rọmọ ete rẹ̀ ijimiji lati mu ki Genesisi 6:13; 7:18.
aiye kun fun awọn atọmọdọmọ ọkunrin ati obirin ekini larin awọn ipo Paradise. Pẹlupẹlu, ila idile ti yio yọrisi pipese Messiah na ni a nilati pamọ. Ni iṣedédé pẹlu eyi, Jehofah sọ fun Noa onigbọran lati kàn ọkọ kan (tabi, apoti kan ti o lefo) ti o tobi lati le gba Noa ati idile rẹ̀ ati awọn iru pataki ninu awọn ẹranko ori ilẹ awọn ẹda ti nfo li ofurufu bi adaba ati ìwô. Ko si yàrá kan ti o ni ẹrọ ti nfi omi ṣiṣẹ tabi ẹrọ ti nlo epo rọ̀bì ati awọn ipese epo lati mu ki ọkọ ṣiṣẹ tabi ẹrọ ti nlo epo rọ̀bì ati awọn ipese epo lati mu ki ọkọ na rin siwaju sibikibi; o wulẹ lefo lori omi ni, pẹlu awọn aláyè ti mbẹ ninu rẹ̀ ati ipese onjẹ ti o to fun ọdun kan tabi jubẹ. —30. Lati mu ki ikun-omi agbaiye bẹ ṣéṣe, kini ipo iṣẹda ti mbẹ nilẹ ati yika aiye lati igba ’ọjọ” iṣẹda keji?
30 Lati loye ṣiṣéṣe ti o ṣéṣe fun iru ikun-omi agbaiye bẹ lati ṣẹlẹ, awa nilati fi oju wo ipo awọn nkan nipa ti aiye wa li apapọ. Li oke rẹ̀ awọn ilẹ wà, nla ati kekeke, ti o ga soke ju awọn okun lọ, Leke gbogbo eyi ni alafo ribiti kan tabi gbangba ofurufu kan wà ti o ni afẹfẹ ninu eyiti araiye ati awọn ohun ẹlẹmi miran nmí sinu. Ṣugbọn rekọja eyi lọ soke ni kubusu olomi jíjìn kan wà ti o yí aiye ká bi igbaja-ọmọ ti Elẹda na si ti mu ki o fò soke si iwọn ti o ṣe déde niti imọ ijinlẹ ni “ọjọ” keji iṣẹda. Nibẹ li o wà ni ìṣorò gẹgẹbi iboju yika agbaiye aiye, lati jábọ pada wa si ilẹ aiye kiki ni ibamu pẹlu ete Ẹlẹda na ati ni aṣẹ Rẹ̀. (Genesisi 1:6-8) Alalaye Bibeli kan ti a misi ni ọgọrun ọdun ekini C.E. ṣapejuwe rẹ̀ daradara, nigbati o wipe: “Awọn ọrun ti wà lati atijọ, ati ti ilẹ yọri jade ninu omi, ti o si duro ninu omi.”—2 Peteru 3:5, NW; Jerusalem, Bible.
31, 32. Kini awọn akọsilẹ Noa fihan nipa ikun-omi na?
31 Ikun-omi agbaiye ki iṣe itan atọwọdọwọ eyiti o ti inu awọn orisun Babiloni jade. O jẹ otitọ itan eyiti o ti fi iyọrisi rẹ̀ silẹ lori ilẹ aiye titi di oni yi. A mọ ọjọ ati akoko rẹ̀. Gẹgẹ bi iwe ọkọ Noa tabi iwe arki ti wi, o bẹrẹ ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu keji ninu ọdun oṣupa, ni ẹgbẹta ọdun iwaláyè rẹ̀.
Genesisi 7:11 titi de 8:19.
32 Nigbana ni Noa ṣe akọsilẹ bibẹsilẹ omi lati ofurufu gẹgẹ bi ohun ti mba a lọ fun ogoji ọjọ. Ani ipari awọn oke ti o wà ni igbana ni ikun omi bò mọlẹ ti o si jin de igbọnwọ mẹdogun. Ni ọjọ kẹtadinlogun ni oṣu keje ti oṣupa, ọkọ na kan ilẹ lẹba awọn oke Ararati. Gẹgẹ bi agbara Ẹlẹda na ti ri, awọn adagun titun li o ṣẹlẹ ni oke ilẹ agbaiye lati fa ikun-omi na mu. Ni ọjọ kini ni oṣu kini ni ọdun oṣupa titun a pari itolẹsẹsẹ fifa omi na. Ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keji ni ọdun oṣupa titun na, tabi ọdun oṣupa kan ati ọjọ mẹwa lẹhinti ikun-omi na bẹrẹ, Ọlọrun sọ fun Noa lati fi ọkọ na silẹ ki o si jẹki gbogbo awọn ẹranko aláyè ti mbẹ ninu rẹ̀ sọkalẹ pẹlu.—33. Kini parun sinu Ikun-omi na, kini si là a já?
33 Lọna bayi, labẹ aábò atọrunwa, iran enia lati ọdọ Adamu la ikun-omi agbaiye na ja, ṣugbọn aiye kan ti ko wà bi Ọlọrun tabi aiye kan ti o jẹ ti awọn alaiwa-bi-Ọlọrun wá si opin. Eyiyi tumọ si pẹlu pe awọn ọmọ ti obi wọn yatọ si ara wọn wọnni, Òmìrán, li a parun, nitoripe nwọn jẹ enia bi gbogbo araiye iyoku. Li ede ti o rọrun ti o si yeni, alalaye Bibeli ọgọrun ọdun ekini na ti a misi ṣapejuwe rẹ̀ daradara, nigbati o wipe:
“Ti (Ọlọrun) ko si dá aiye igbánì si, ṣugbọn o pa Noa pẹlu awọn meje miran mọ́, oniwasu ododo, nigbati o mu kikun omi wá sori aiye awọn alaiwa-bi-Ọlọrun: . . . Nipa eyiti omi bo aiye ti o wà nigbana, ti o si ṣegbe.”—2 Peteru 2:5; 3:6.
34. Gẹgẹ bi Mose ti wi, kini ṣẹlẹ si awọn ẹda aláyè lori ilẹ aiye ati si awọn wọnni ti mbẹ ninu ọkọ arki?
34 Eyiyi ṣe dédé pẹlu ọrọ woli na Mose: “Gbogbo ohun ti ẹmi iye wà ni iho imu rẹ̀, gbogbo ohun ti o wà ni iyangbẹ ilẹ si ku. Ohun aláyè gbogbo ti o wà lori ilẹ li a si parun, ati enia, ati ẹran-ọsin, ati ohun ti nrako, ati ẹiyẹ oju-ọrun, nwọn si run kuro lori ilẹ. Noa nikan li o kù, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ. Omi si gbilẹ li adọjọ ọjọ li aiye.”—Genesisi 7:22-24.
35. Bi awa ko ba fẹ pe ki a pa wa mọ de “ọjọ ibi?” ti Ọlọrun yio mu idajọ ṣẹ, kini awa nilati ṣe nisisiyi, gẹgẹ bi Noa?
2 Peteru 2:9) “(Jehofah) ti ṣe ohun gbogbo fun ipinnu rẹ̀, nitôtọ, ani awọn enia buburu fun ọjọ ibi.” (Owe 16:4) Nitorina, nigbana, bi awa ko ba fẹ ki a fi wa fun “ọjọ ibi” ti mbọ kánkán yi, “ọjọ’’ Jehofah ti o ti diwọn funrarẹ̀ fun mimu idajọ ododo rẹ̀ ṣẹ sori gbogbo awọn enia alaiṣoôtọ lori ilẹ aiye, o lọgbọn ninu fun wa lati ba Ọlọrun rin, gẹgẹ bi Noa ti ṣe, ki a si faramọ ete Rẹ̀.
35 Ikun-omi yi ti o kari aiye nitotọ jẹ “iṣe Ọlọrun.” O ṣapejuwe lọna iyanu koko kan ti awa ti mbẹ loni nilati fi ọkàn si. Koko wo ni? ”(Jehofah) mọ bi a ti iyọ awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun kuro ninu idanwo, ati bi a ti ipa awọn alaiṣôtọ ti a njẹ niya mọ de ọjọ idajọ.“ (36. (a) Nigba Ikun-omi na, kini ṣẹlẹ si awọn Òmìrán na? (b) Pẹlupẹlu, iyọrisi wo li o de ba “awọn ọmọ Ọlọrun otitọ” alaigbọran wọnni?
36 Nigba Ikun-omi na, ki iṣe kiki awọn alaiṣododo ati awọn Òmìrán nikan li a mu idajọ atọrunwa ṣẹ sori wọn, ṣugbọn sori awọn ọmọ Ọlọrun alaigbọran wọnni ti o ni iriri idajọ ti o yẹ lodi si wọn. Nitotọ, nigbati Ikun-omi na bò aiye gbogbo, awọn ’’ọmọ Ọlọrun otitọ” wọnni fi awọn aya wọn silẹ ati idile wọn ti nwọn si bẹ enia silẹ, nwọn ko si rì. Ṣugbọn nigbati nwọn pada si ipo wọn ti ẹmi nkọ, eyiti o jẹ ibi yiyẹ fun wọn lati má gbe. Nwọn ha tun bẹrẹ isopọ timọtimọ ti nwọn ti ni pẹlu Ọlọrun tẹlẹ? Ibatan wọn pẹlu Rẹ̀ ha ri bakanna bi ti atẹhinwa bi? Nwọn ha mba a lọ ninu eto mimọ rẹ̀ ti ọrun gẹgẹ bi awọn “ọmọ Ọlọrun” sibẹ? Bẹkọ; ṣugbọn ninu awọn ẹda ẹmi alaigbọran wọnyi li a ri ibẹrẹ “awọn ẹmi eṣu!” (yatọ si Satani Eṣu) eyiti woli Mose sọrọ nipa rẹ̀. (Deuteronomi 32:17; pẹlupẹlu Orin Dafidi 106:3) Ṣugbọn awọn alalaye Bibeli ti ọgọrun ọdun ekini ṣe pato ju nipa bi Jehofah Ọlọrun ṣe ba awọn ẹda ẹmi alaigbọran wọnni lò, nigbati nwọn wipe:
“Awọn angeli ti ko tọju ipo ọla wọn, ṣugbọn ti nwọn fi ipo wọn silẹ, awọn ni o pamọ ninu ẹwọn ainipẹkun nisalẹ Juda 6) “Awọn ẹmi ninu tubu: awọn ti o ṣaigbọran nigba kan, nigbati sùúrù Ọlọrun duro pẹ́ ni sa kan ni ọjọ Noa, nigbati nwọn fi nkàn ọkọ ninu eyiti a gba ọkan diẹ là nipa omi, eyini ni ẹni mẹjọ.” (1 Peteru 3:19, 20) “Bi Ọlọrun ko ba dá awọn angeli si ti nwọn ṣẹ̀, ṣugbọn ti o sọ wọn si isalẹ ọrun apadi (Tartaru), ti o si fi wọn sinu ọgbun okunkun biribiri, awọn ti a pamọ de idajọ.”—2 Peteru 2:4.
okunkun de idajọ ọjọ nla nì.” (37. Nigbati nwọn padabọ si ilẹ ọba ẹmi, kini ipo ti “awọn ọmọ Ọlọrun otitọ” alaigbọran” wọnni wa?
37 Nitorina bibọ ti “awọn ọmọ Ọlọrun” alaigbọran bọ awọ enia silẹ ati pipada wọn lọ si ọrun ilẹ ọba ẹmi ko yí wọn pada si awọn angeli mimọ lẹkan si i. Nwọn ba ara wọn ni iha ọdọ Satani Eṣu, ọlọtẹ akọkọ lodi si Jehofah Ọlọrun. Nwọn ko yẹ fun ibikan mọ ninu eto ọrun mimọ Jehofah ti o dabi iyawo ti o jẹ ti “awọn Ọmọ Ọlọrun” onigbọran. Nitori idi eyi a rẹ̀ wọn silẹ si ipo “awọn ẹmi eṣu.” Ipo irẹsilẹ, alailọwọ yi li a sọrọ rẹ̀ bi o ti tẹ gẹgẹ bi Tartaru, orukọ kan ti a yálò lati ede Griki. Itẹjade Bibeli li ede Siria sọrọ rẹ̀ gẹgẹ bi “awọn ibi ti o rẹlẹ julọ.” (Tun wo Jobu 40:15; 41:23 ninu Septuagimt Version ti Griki.) Awọn ẹda ẹmi alaigbọran wọnni li a ko tun ṣe ojurere si mọ pẹlu ilaloye ti ẹmi gẹgẹ bi iru eyiti Ọlọrun ri pe o yẹ lati fifun awọn angeli ọmọ rẹ̀ oloôtọ. Li ọna bayi, a jù wọn sinu okunkun biribiri a si dé wọn mọ ibẹ bi ẹnipe pẹlu ‘’ẹ̀wọ̀n aiyeraiye,” lati pa wọn mọ de “idajọ ọjọ nla nì.” Nitorina nwọn ko le fun araiye ni ilaloye tôtọ kankan.
38. “Iru-ọmọ” tani ni awọn ẹda ẹmi alaigbọran wọnni dà, bawo ni nwọn si ti ṣe nṣiṣẹ si itanjẹ ati ikolẹru enia?
38 Iru awọn ẹda ẹmi alaigbọran bẹ di “iru-ọmọ” Ejo Nla na, Satani Eṣu ti a ko le fojuri. Fifi ti a fi wọn sinu ‘’okunkun biribiri’’ ti o dabi Tartaru pẹlu Satani Eṣu ki iṣe fifọ ori ejo na lati ọwọ “iru-ọmọ” obirin” Ọlọrun li ọrun. “Iru-ọmọ” mimọ na li a koiti pese sibẹ, awọn ẹmi buburu ti a si ju sinu ẹwọn si nfẹ lati mọ ẹniti on yio jẹ ki nwọn ba le darapọ ni pipa ‘’gigisẹ̀” “iru-ọmọ” na. (Genesisi 3:15) Fun idi eyini awọn ẹmi buburu wọnni labẹ Satani olori wọn nsunmọ iran enia, lati tan wọn jẹ ki nwọn si yi wọn pada lodi si “iru-ọmọ” na nigbati o ba de. Nwọn gbiyanju lati ba awọn enia sọrọ nipasẹ awọn abẹmilo, niwọnbi awọn funrawọn ti di ẹniti a ká lọwọ kò lati parada di enia. Nwọn díbọn lati di “ọkàn ti o bọ ara silẹ” ti iṣe ti awọn oku enia. Nwọn kún ọkàn tabi dabaru ọkàn awọn enia alailagbara, ani nwọn tilẹ nṣakoso awọn enia ti o ba gbọjẹgẹ fun wọn. Woli Mose li a misi lati kilọ fun awọn enia Ọlọrun pe ki nwọn maṣe ní ohunkohun iṣe pẹlu awọn ẹmi eṣu ọta Ọlọrun wọnyi. (Deuteronomi 18:9-13) Nitorina yẹra fun biba-ẹmi-lo.
39. Bi ki ba ṣe si awọn ẹmi eṣu, nigbana tani awa nilati yiju si fun ilaloye ti ẹmi?
39 Niwọnbi awa ti nfẹ ilaloye lori ‘’ete aiyeraiye” Jehofah Ọlọrun, awa nilati yẹra fun awọn agbara ẹmi okunkun wọnni eyiti o nfọ eyiti o pọ julọ ninu araiye loju si otitọ Ọlọrun. Ọrọ Ọlọrun ti a kọwe rẹ̀ silẹ, Bibeli Mimọ, jẹ ọna ilaloye ti ẹmi fun wa, gẹgẹ bi awọn ọrọ onipsalmu na ti a misi ti wi, nigbati o wi fun Jehofah Ọlọrun pe: Ọrọ rẹ ni fitila si mi li ẹsẹ, ati imọlẹ si ipa ọna mi.”—Orin Dafidi 119:105.
40. Laibikita fun iṣọtẹ awọn enia ati angeli, kini wa nibẹ lati fihan fun iṣotitọ niha ọdọ eto Ọlọrun li ọrun ati isowọpọ rẹ̀?
40 Ninu ìmọlẹ Ọrọ Ọlọrun awa ti bojuwo ẹhin rekọja si 1,656 ọdun ekini ninu i waláyè enia lori ilẹ iye, lati iṣẹda Adamu titi di igba ikun-omi ọjọ Noa. Laibikita fun iṣọtẹ awọn angeli ati awọn enia, Ọlọrun ti ko le yipada na rọ̀ mọ ete rẹ̀ akọkọ nipa araiye lori ilẹ aiye. Biotilẹjẹpe aimoye awọn angeli li o juwọ silẹ fun ifẹ imọti-ara-ẹni nikan ti nwọn si dẹṣẹ ti nwọn si yẹ fun iyọlẹgbẹ kuro ninu eto ọrun ti o dabi iyawo, awọn wọnyi ko dabi awọn wọnni ti o ṣe olótọ si I lárin eto mimọ rẹ̀, bi olôtọ aya si ọkọ onifẹ kan.Ẹgbẹgbẹrun ọdun lẹhinna woli Danieli ri ninu iran adọta ọkẹ lọna ọgọrun awọn angeli olôtọ ti nwọn ṣi njiṣẹ fun Ọlọrun Ọga Ogo Julọ, “Ẹni Agba Ọjọ nì. (Danieli 7:9, 10) “Obirin” ọrun yi, ti yio jẹ iya fun “iru-ọmọ” ti a sọtẹlẹ na li ọjọ iwaju, li a gbekalẹ gẹgẹ bi “ọta” Ejo Nla na, Satani Eṣu, ati “iru-ọmọ”rẹ̀. On pinnu gidigidi lati sowọpọ pẹlu Jehofah Ọlọrun ninu ilepa ete rẹ̀ titun ti a ṣẹṣẹ kede lati mu “iru-ọmọ” na jade li akoko rẹ̀ ti o yàn.
41 Lori ilẹ aiye ninu Paradise Igbadun, a ti sọ Adamu ati Efa di apakan eto agbaiye Jehofah ti a le fojuri nigba iṣẹda wọn ninu ijẹpipe enia. Labẹ idanwo nwọn ko di iduroṣinṣin wọn mu si Ẹlẹda wọn, Baba wọn ọrun. Labẹ idajọ iku a lé wọn jade kuro ninu eto agbaiye Jehofah nwọn si dẹkun lati di ẹniti a kakun awọn ọmọ Rẹ̀. Ṣugbọn nipa ti awọn ọmọ wọn nkọ? Lati wò o lati ọdọ Adamu ati Efa awọn oluba-idu-roṣinṣin-jẹ, awọn ọmọ wọn ti a bi li aipe, ti o si jogun ẹṣẹ ko ni yẹ lati di iduroṣinṣin mu si Ẹlẹda wọn labẹ idanwo ati ikimọle lati ọdọ Satani Ẹsu, Ejo Nla na. O han gbangba pe, Satani Eṣu gbèrò lati fihan niwaju gbogbo ẹda li ọrun ati li aiye pe ko si ọ̀kan ninu wọn ti yio ṣe bẹ. On ha mu koko rẹ̀ ṣẹ bi, ani ṣáju Ikun-omi? Akọsilẹ Bibeli ti o fi ero Ọlọrun han lori ọrọ yi fihan pe o kere tan awọn ọkunrin mẹta di iduroṣinṣin wọn mu, eyini ni, Abeli, Enoku ati Noa.
42, 43. (a) Ọran Abeli, Enoku ati Noa gbe ẹri wo kalẹ? (b) Bawo ni iriran-jinna Jehofah ṣe múná nipa pipese ẹri siwaju si i?
42 Awọn ọkunrin mẹta oloôtọ, olubẹru Ọlọrun wọnni di ipo Jehofah Ẹlẹda wọn mu gẹgẹ bi ọba alaṣẹ agbaiye. Nwọn fihan pe Satani Eṣu jẹ agberaga eleke ni jijiyan pe Ọlọrun Olodumare ko le ní ọkunrin kan lori ilẹ aiye, pápá ninu ayika oni-Paradise kan, ti yio di iduroṣinṣin rẹ̀ mu si Jehofah nigbati a ba fi i sabẹ awọn idanwo ati awọn ikimọlẹ Satani Eṣu. Ọran Abeli, Enoku ati Noa fihan pe Ọlọrun Ẹlẹda li a dalare ni fifi àyè silẹ fun iran enia, ti o wá lati ọdọ Adamu ati Efa ẹlẹṣẹ, lati má ba a niṣo lati walaye lori ilẹ aiye. Awọn ọkunrin miran, pẹlu awọn obirin, ni afikun si Abeli, Enoku ati Noa daju pe nwọn yio farahan ninu awọn ẹgbẹ araiye bi iwaláyé enia ti ntẹsiwaju lori ilẹ aiye lẹhin ode Paradise, nipa bayi ki
ẹri pelemọ si wà lodi si irọ Eṣu ati ibalorukọjẹ si Ọlọrun.43 Iriran-jinna Jehofah múná, ete rẹ̀ si daju lati ni imuṣẹ. Ete Messiah rẹ̀ ti a kede niwaju Ejo Nla na ninu ọgba Edeni fi agbara kún ete Ọlọrun akọkọ o si mu imuṣẹ rẹ̀ daju. Ipo ọba alaṣẹ agbaiye Ọlọrun lori ilẹ aiye, gẹgẹ bi a ti fihan lọna agbara ninu ikun-omì agbaiye, ko ni dẹkun lori araiye.
[Ibeere]
11. Asọtẹlẹ wo ni Enoku sọ, lori ipo wo ti awọn enia si wa li a nilati fi eyi han?
27. Kini Ọlọrun pete lati wẹ̀ mọ kuro lori ilẹ aiye, esitiṣe?
41. Koko wo ni Satani fi pẹlu ìkà pete lati fihan niwaju gbogbo ẹda, on ha si ṣe aṣeyọri kikun pápá ṣaju Ikun-omi na bi?