Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ Bibeli Ní Kedere Ha Ni Bí?

Ẹ̀kọ́ Bibeli Ní Kedere Ha Ni Bí?

Ẹ̀kọ́ Bibeli Ní Kedere Ha Ni Bí?

BÍ MẸTALỌKAN bá jẹ́ otitọ, a gbọdọ gbé é kalẹ̀ ninu Bibeli lọna ti o ṣe kedere tí ó sì baramu. Eeṣe? Nitori pe, gẹgẹ bi awọn apọsiteli ti tẹnumọ ọn, Bibeli jẹ́ ìṣípayá Ọlọrun fúnraarẹ̀ fun aráyé. Niwọn bi ó sì ti jẹ́ ọ̀ranyàn lati mọ̀ Ọlọrun lati le jọsin rẹ̀ lọna tí ó ṣè ìtẹ́wọ́gbà, Bibeli gbọdọ ṣe kedere ninu sísọ fun wa ẹni tí oun jẹ́ gan-an.

Awọn onígbàgbọ́ ọgọrun-un ọdun kìn-ínní tẹwọgba Iwe Mimọ gẹgẹ bi ìṣípayá ti o ṣeegbarale lati ọdọ Ọlọrun. Oun ní ìpìlẹ̀ fun ìgbàgbọ́ wọn, àṣẹ ikẹhin. Fun apẹẹrẹ, nigba ti apọsiteli Pọọlu waasu fun awọn eniyan ní ìlú Beria, “wọn gbà ọ̀rọ̀ naa pẹlu iharagaga ero inu titobi julọ, wọn nfarabalẹ ṣàyẹ̀wò awọn Iwe Mimọ lojoojumọ boya awọn nǹkan wọnyi rí bẹẹ.”​—⁠Iṣe 17:​10, 11New World Translation of the Holy Scriptures.

Ki ni awọn eniyan Ọlọrun tí wọn lokiki ní akoko yẹn ńlò gẹgẹ bi àṣẹ wọn? Iṣe 17:​2, 3 (NW), sọ fun wa pe: “Gẹgẹ bi àṣà Pọọlu . . . oun ńronúpọ̀ pẹlu wọn lati inu awọn Iwe Mimọ, ó ńṣàlàyé ó si nfi ẹri han nipasẹ awọn ìtọkasí [lati inu awọn Iwe Mimọ].”

Jesu fúnraarẹ̀ fi apẹẹrẹ lélẹ̀ ní lílò Iwe Mimọ gẹgẹ bi ipilẹ fun ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ní sísọ leralera pe: “A ti kọ ọ́ pe.” “Ó si ntúmọ̀ nǹkan fun wọn ninu Iwe Mimọ gbogbo nipa ti ara rẹ.”​—⁠Matiu 4:​4, 7; Luuku 24:⁠27.

Nipa bayii, Jesu, Pọọlu, ati awọn onígbàgbọ́ ní ọgọrun-un ọdun kìn-ínní lò Iwe Mimọ gẹgẹ bi ipilẹ̀ fun ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wọn. Wọn mọ̀ pe “gbogbo Iwe Mimọ ni Ọlọrun mísí ti ó sì ṣanfaani fun ẹkọ, itọnisọna, fun mímú awọn nǹkan tọ́, fun bíbániwí ninu òdodo, kí eniyan Ọlọrun lè pegede ni kíkún, tí a mu gbaradi fun iṣẹ́ rere gbogbo.”​—⁠2 Timoti 3:​16,17, NW; tún wo 1 Kọrinti 4:⁠6; 1 Tẹsalonika 2:13; 2 Peteru 1:​20, 21.

Niwọn bi Bibeli ti lè ‘mú awọn nǹkan tọ́,’ ó nilati ṣípaya isọfunni nipa ọran kan ti o jẹ ipilẹ bi a ti sọ pe Mẹtakọkan jẹ. Ṣugbọn ǹjẹ́ awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn tabi awọn òpìtàn fúnraawọn ha sọ pe ẹ̀kọ́ Bibeli ni kedere ni bi?

“Mẹtalọkan” Ha Wà Ninu Bibeli Bí?

ITẸJADE Protẹsitanti kan sọ pe: “Ọ̀rọ̀ naa Mẹtalọkan ni a kò rí ninu Bibeli . . . Ko ri aye fun itẹwọgba gbogbogboo ninu ẹkọ isin ṣọọṣi titi di ọgọrun-un ọdun kẹrin.” (The Illustrated Bible Dictionary) Aláṣẹ Katoliki kan sì sọ pe Mẹtalọkan ‘kìí ṣe . . . ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní tààràtà tabi ni ibaṣepọ kankan pẹlu rẹ.”​—⁠New Catholic Encyclopedia.

The Catholic Encyclopedia bakan naa ṣalaye pe: “Ninu Iwe Mimọ kò sí ọ̀rọ̀ kankan tí a lò lati fi tọkasi awọn Ẹni Ọ̀run Mẹta naa papọ̀. Ọ̀rọ̀ naa τρίας [triʹas] (tí trinitas, ọ̀rọ̀ Latini naa jẹ́ ìtumọ̀ rẹ̀) ni a kọ́kọ́ rí ninu Theophilus ti Antioku ní nǹkan bii A.D. 180. . . . Láípẹ́ lẹhin naa ó farahan nínú oríṣi èdè Latini rẹ̀ ti trinitas ninu Tertullian.”

Bi o ti wu ki o rí, eyi kìí ṣe ẹ̀rí ninu araarẹ̀ pe Tertullian kọ́ni ní Mẹtalọkan. Iwe Katoliki naa Trinitas​—⁠A Theological Encyclopedia of the Holy Trinity, fun apẹẹrẹ, ṣakiyesi pe diẹ lara awọn ọ̀rọ̀ Tertullian ni awọn ẹlomiran lò nigba ti ó ya lati ṣapejuwe Mẹtalọkan. Lẹhin naa o kìlọ̀ pe: “Ṣugbọn awọn ipinnu akanjuṣe ni a kò lè rí fàyọ lati inu lílò rẹ̀, nitori pe oun kò lò awọn ọ̀rọ̀ naa fun ẹ̀kọ́ ìsìn Mẹtalọkan.”

Awọn Ẹri Lati Inu Iwe Mimọ Lédè Heberu

NIGBA ti ó jẹ́ pe a kò rí ọ̀rọ̀ naa “Mẹtalọkan” ninu Bibeli, ó kérétán èrò nipa Mẹtalọkan ni a ha fi kọ́ni ni kedere ninu rẹ̀ bi? Fun àpẹẹrẹ, ki ni Iwe Mimọ lédè Heberu (“Majẹmu Laelae”) ṣípayá?

The Encyclopedia of Religion gbà pe: “Awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn lonii wà ní ìfohùnṣọ̀kan pe Bibeli lédè Heberu kò ní ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ninu.” New Catholic Encyclopedia sì sọ pẹlu pe: “Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan Mímọ́ ni a kò fi kọ́ni ninu M[ajẹmu] L[aelae].”

Ni ifarajọra, ninu iwe rẹ̀ The Triune God, onísìn Jesuit naa Edmund Fortman gbà pe: “Majẹmu Laelae . . . kò sọ ohunkohun fun wa lọna ṣiṣe kedere tabi dọgbọn túmọ̀sí Ọlọrun Mẹ́ta-nínú-ọ̀kan tí ó jẹ́ Baba, Ọmọkunrin, ati Ẹ̀mí Mímọ́ . . . Kò sí ẹ̀rí kankan pe òǹkọ̀wé awọn ọrọ mímọ́ eyikeyii tilẹ̀ fura sí wíwà [Mẹtalọkan] kan laaarin Ọlọrun ẹlẹni mẹta. . . . Kódà lati rí awọn idamọran tabi awọn òjìji tabi ‘awọn àmì tí wọn farasin’ ninu [Majẹmu Laelae] nipa awọn ẹda mẹtalọkan, jẹ́ lati rekọja awọn ọ̀rọ̀ ati ète awọn òǹkọ̀wé awọn ọrọ mímọ́.”​—⁠Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ tiwa.

Àyẹ̀wò awọn Iwe Mimọ lédè Heberu fúnraawọn yoo jẹrii si awọn alaye wọnyi. Nipa bayii, kò sí ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ṣiṣe kedere kankan ninu iwe 39 àkọ́kọ́ ninu Bibeli tí ó parapọ̀ jẹ́ ìwé-onímìísí tootọ ti Iwe Mimọ lede Heberu tí a mísí.

Awọn Ẹri Iwe Mimọ Lédè Giriiki

ÓDÁRA, nigba naa, njẹ Iwe Mimọ Kristẹni lédè Giriiki (“Majẹmu Titun”) ha sọ̀rọ̀ lọna ṣiṣe kedere nipa Mẹtalọkan bi?

The Encyclopedia of Religion sọ pe: “Awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn fohunṣọkan pe Majẹmu Titun pẹlu kò ní ẹ̀kọ́ ṣiṣe kedere nipa Mẹtalọkan ninu.”

Onísìn Jesuit naa Fortman sọ pe: “Awọn òǹkọ̀wé Majẹmu Titun . . . kò fún wa ní ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan alaiṣepato tabi alakọsilẹ eyikeyii, kò sí ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kedere kankan pe ninu Ọlọrun kan ni awọn ẹni ti ọ̀run abáradọ́gba mẹta wà . . . Kò sí ibikibi tí a ti rí ẹ̀kọ́ mẹtalọkan eyikeyii nipa awọn ẹni mẹta ọtọọtọ tí wọn ní iwalaaye ati ìgbòkègbodò ti ọ̀run ninu Ọlọrun ẹlẹni mẹta kan naa.

The New Encyclopædia Britannica ṣakiyesi pe: “Yálà ọ̀rọ̀ naa Mẹtalọkan tabi ẹ̀kọ́ naa tí ó ṣe kedere ko farahàn ninu Majẹmu Titun.”

Bernhard Lohse sọ ninu A Short History of Christian Doctrine pe: “Niti Majẹmu Titun, ẹni kan kò lè rí ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan pato kankan ninu rẹ̀.”

The New International Dictionary of New Testament Theology bakan naa sọ pe: “M[ajẹmu] T[itun] kò ní ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan tí a mu gbèrú ninu. ‘Kò sí ipolongo kankan ti a sọjade ninu Bibeli pe Baba, Ọmọkunrin, ati Ẹ̀mí Mímọ́ ní ìpilẹ̀ ọgbọọgba’ [ni ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Protẹsitanti naa Karl Barth sọ].”

Ọ̀jọ̀gbọ́n E. Washburn Hopkins ti Yunifasiti Yale polongo pẹlu ìdánilójú pe: “Sí Jesu ati Pọọlu lọna híhàn gbangba ẹ̀kọ́ mẹtalọkan jẹ ohun ajeji; . . . wọn kò sọ ohunkohun nipa rẹ̀.”​—⁠Origin and Evolution of Religion.

Òpìtàn Arthur Weigall ṣakiyesi pe: “Jesu Kristi kò mẹnuba iru ohun àrà bẹẹ nígbà kankan rí, kò sì sí ibikibi ninu Majẹmu Titun tí ọ̀rọ̀ naa ‘Mẹtalọkan’ ti farahàn. Èrò naa ni Ṣọọṣi wulẹ̀ gbà ní ọgọrun-un ọdun mẹta lẹhin ikú Oluwa wa.”​—⁠The Paganism in Our Christianity.

Nipa bayii, kìí ṣe yálà iwe 39 ti awọn Iwe Mimọ lédè Heberu tabi ìwé onímìísí 27 ti awọn Iwe Mimọ Kristẹni lédè Giriiki ní ó pèsè ẹ̀kọ́ ṣiṣe kedere eyikeyii nipa Mẹtalọkan.

Awọn Kristẹni Ijimiji Ha Fi Kọ́ni Bí?

NJẸ awọn Kristẹni ijimiji ha fi Mẹtalọkan kọ́ni bí? Ṣakiyesi awọn alaye tí wọn tẹ̀lé e yii lati ọ̀dọ̀ awọn òpìtàn ati awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn:

“Isin Kristẹni ijimiji kò ní ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ti a gbekalẹ lọna ti o ṣe kedere iru eyi ti a wá ṣalaye fínnífínní lẹhin naa ninu awọn ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́.”​—⁠The New International Dictionary of New Testament Theology.

“Awọn Kristẹni ijimiji, bi o ti wu ki o ri, lákọ̀ọ́kọ́ kò ronú nipa fifi èrò [Mẹtalọkan] kun igbagbọ tiwọn funraawọn. Wọn nfi ìfọkànsìn wọn fun Ọlọrun Baba ati fun Jesu Kristi, Ọmọkunrin Ọlọrun, wọn sì mọ̀ . . . Ẹ̀mí Mímọ́ dájúṣáká; ṣugbọn kò sí èrò kankan pe awọn mẹta wọnyi jẹ́ Mẹtalọkan niti tootọ, tí wọn jẹ ọgbọọgba tí wọn sì sopọ̀ ṣọ̀kan ní Ọ̀kanṣoṣo.”​—⁠The Paganism in Our Christianity.

“Lákọ̀ọ́kọ́ igbagbọ Kristẹni kìí ṣe ẹlẹkọọ Mẹtalọkan . . . Kò rí bẹẹ ní awọn sanmani awọn apọsiteli ati lẹhin ìgbà awọn apọsiteli, gẹgẹ bi a ti fihàn nínu M[ajẹmu] T[itun] ati awọn ìkọ̀wé Kristẹni ijimiji miiran.”​—⁠Encyclopædia of Religion and Ethics.

“Ìgbékalẹ̀ ‘Ọlọrun kan ninu ẹni mẹta’ kò fìdímúlẹ̀ gbọnyingbọnyin, dajudaju eyi kò wọ̀ inú ìgbésí-ayé Kristẹni ati ìjẹ́wọ́ igbagbọ rẹ̀, ṣaaju opin ọgọrun-un ọdun kẹrin. . . . Laaarin awọn onkọwe lẹhin akoko awọn Apọsiteli kò sí ohunkohun àní tí ó fẹrẹẹ súnmọ́ èrò orí tabi ọ̀nà ìwòye kan bẹẹ.”​—⁠New Catholic Encyclopedia.

Ohun Tí Awọn Onkọwe Ṣaaju Ìgbà Nicaea Fi Kọ́ni

AWỌN Onkọwe ṣaaju ìgbà Nicaea ní a mọ̀ dájú pe wọn jẹ́ awọn olukọ ẹ̀kọ́ ìsìn onipo iwájú ni awọn ọgọrun-un ọdun akọkọ lẹhin ikú Kristi. Ohun tí wọn fi kọ́ni jẹ́ ohun tí a lè nifẹẹ sí.

Justin Martyr, tí ó kú ní nǹkan bíi 165 C.E., pè Jesu ṣaaju kí ó tó di ẹ̀dá ènìyàn ní angẹli kan tí a dá tí ó wà “yàtọ̀ sí Ọlọrun tí ó ṣe ohun gbogbo.” Ó sọ pe Jesu rẹlẹ̀ sí Ọlọrun ti “kò sì ṣe ohunkohun àyàfi ohun tí Ẹlẹdaa . . . nfẹ kí ó ṣe tabi kí ó sọ.”

Irenaeus, tí ó kú ní nǹkan bii 200 C.E., sọ pe Jesu ṣaaju ki o to di ẹ̀dá ènìyàn wà lọ́tọ̀ ó sì rẹlẹ̀ sí Ọlọrun. Ó fihan pe Jesu kò dọ́gba pẹlu “Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa,” tí ó jẹ́ “onípò àjùlọ lori ohun gbogbo, ati lẹhin ẹni tí kò sí ẹlomiran kankan.”

Clement ti Alẹksandria, tí ó kú ní nǹkan bii 215 C.E., pè Ọlọrun ní “Ọlọrun tootọ kanṣoṣo aláìlèṣègbé tí a kò ṣẹ̀dá.” Ó sọ pe Ọmọkunrin naa “wà ní ipò keji sí Baba kanṣoṣo naa tí ó jẹ́ Olodumare” ṣugbọn kò bá a dọ́gba.

Tertullian, tí ó kú ní nǹkan bii 230 C.E., fi jijẹ ẹni giga julọ Ọlọrun kọ́ni. Oun ṣakiyesi pe: “Baba yàtọ̀ sí Ọmọkunrin (ẹlomiran), niwọn bi o ti tobi ju; niwọn bi o ti jẹ pe ẹni ti o muni walaaye yàtọ̀ sí ẹni naa tí a mú wàláàyè; ẹni tí ó ránni, yàtọ̀ sí ẹni naa tí a rán.” Oun tún sọ pe: “Akoko kan wà nigba ti Ọmọkunrin kò sí. . . . Ṣaaju ohun gbogbo, Ọlọrun wà ní oun nìkanṣoṣo.”

Hippolytus, tí ó kú ní nǹkan bíi 235 C.E., sọ pe Ọlọrun jẹ́ “Ọlọrun kanṣoṣo naa, ẹni àkọ́kọ́ ati Ẹni kanṣoṣo, Olùṣe ati Oluwa ohun gbogbo, ẹni tí “kò ní ẹnikẹni ti o jẹ ẹgbẹ niti akoko [tí ó jẹ ọlọjọ ori kan naa] pẹlu rẹ̀ . . . Ṣugbọn oun jẹ́ Ọ̀kanṣoṣo, tí ó dáwà ní òun nìkan, ẹni tí, pẹlu ìfẹ́-inú rẹ̀, mu ohun tí kò wà ṣaaju di ohun tí ó wà,” irú bii Jesu ti a ṣẹda ẹni ti o ti walaaye ṣaaju ki o to di eniyan.”

Origen, tí ó kú ní nǹkan bíi 250 C.E., sọ pe “Baba ati Ọmọkunrin jẹ́ awọn ẹni meji . . . awọn ẹni meji niti ijẹpataki,” ati pe “bí a bá fiwé Baba, [Ọmọkunrin] jẹ́ ìmọ́lẹ̀ kekere gan-an.”

Ní ṣíṣàkópọ̀ awọn ẹri inu ìtàn, Alvan Lamson sọ ninu The Church of the First Three Centuries pe: “Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan tí ó gbajúmọ̀ lóde-òní . . . kò rí ìtìlẹ́hìn kankan lati inu èdè Justin [Martyr]: akiyesi yii ni a sì lè nasẹ rẹ dé ọ̀dọ̀ gbogbo awọn onkọwe tí wọn wà ṣaaju ìgbà Nicaea; iyẹn ni pe sí gbogbo awọn òǹkọ̀wé Kristẹni fun ọgọrun-un ọdun mẹta lẹhin ìbí Kristi. Ootọ ni pe, wọn sọ nipa Baba, Ọmọkunrin, ati . . . Ẹ̀mí mímọ́, ṣugbọn kìí ṣe gẹgẹ bi ọgbọọgba, kìí ṣe gẹgẹ bi ẹda ẹlẹ́ni kanṣoṣo, kìí ṣe gẹgẹ bi Mẹta ninu Ọ̀kan, ní ìtúmọ̀ eyikeyii tí awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹtalọkan gbà nisinsinyi. Odikeji rẹ gan-an ni òtítọ́ naa.”

Nipa bayii, ẹ̀rí Bibeli ati ti ìtàn mú un ṣe kedere pe Mẹtalọkan ni a kò mọ̀ jálẹ̀jálẹ̀ awọn akoko Bibeli ati fun ọpọlọpọ ọgọrun-un ọdun lẹhin naa.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

“Kò sí ẹ̀rí pe òǹkọ̀wé awọn ọrọ mímọ́ eyikeyii tilẹ̀ fura sí wíwà [Mẹtalọkan] kan tí ó wà ninu Ọlọrun ẹlẹni mẹta.”​—⁠The Triune God