Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀mí Mímọ́—Ipá Agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun

Ẹ̀mí Mímọ́—Ipá Agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun

Ẹ̀mí Mímọ́—⁠Ipá Agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun

GẸGẸ bi ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ti wi, ẹ̀mí mímọ́ ni ẹni kẹta ninu Ọlọrun ẹlẹni mẹ́ta, tí ó bá Baba ati Ọmọkunrin dọ́gba. Gẹgẹ bi iwe naa Our Orthodox Christian Faith ti sọ: “Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ Ọlọrun pátápátá.”

Ninu Iwe Mimọ lédè Heberu, ọ̀rọ̀ tí a ńlò lọna tí ó ṣe lemọlemọ julọ fun “ẹ̀mí” ni ruʹach, tí ó tumọsi “èémí; afẹ́fẹ́; ẹ̀mí.” Ninu Iwe Mimọ lédè Giriiki, ọ̀rọ̀ naa ni pneuʹma, tí ó ní ìtumọ̀ tí ó farajọra. Awọn ọ̀rọ̀ wọnyi ha fihan pe ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ apákan Mẹtalọkan bi?

Ipá Agbékánkánṣiṣẹ́ Kan

BÍ BIBELI ṣe ńlò “ẹ̀mí mímọ́” fihan pe ó jẹ́ ipá kan tí a ńṣàkóso eyi tí Jehofa Ọlọrun ńlò lati ṣàṣeparí oniruuru awọn ète rẹ̀. Dé àyè kan pàtó, a lè fiwé iná mànàmáná, ipá kan tí a lè ṣeto lati ṣe oniruuru awọn iṣẹ́ ńláǹlà.

Jẹnẹsisi 1:⁠2 (NW), Bibeli sọ pe “ipá agbékánkánṣiṣẹ́ [“ẹ̀mí” (Heberu, ruʹach)] Ọlọrun ńlọ́ síwá ati sẹ́hìn lori awọn omi.” Níhìn-ín, ẹ̀mí Ọlọrun jẹ́ ipá agbékánkánṣiṣẹ́ rẹ̀ tí ó ńṣiṣẹ́ lati mú ilẹ̀-ayé jáde.

Ọlọrun ńlò ẹ̀mí rẹ̀ lati fun awọn wọnni tí wọn nṣiṣẹsin in ni oye. Dafidi gbadura pe: “Kọ́ mi lati ṣe ìfẹ́ inú rẹ, nitori iwọ ni Ọlọrun mi. Ẹ̀mí [ruʹach] rẹ dára; jẹ́ kí ó fà mi lọ ní ilẹ̀ adúróṣánṣán.” (Saamu 143:10, NW) Nigba ti a yàn 70 awọn ọkunrin dídáńgajíá lati ran Mose lọwọ, Ọlọrun sọ fun un pe: “Emi yoo sì mú ninu ẹ̀mí [ruʹach] tí ńbẹ lara rẹ̀, emi yoo sì fi sára wọn.”​—⁠Numeri 11:⁠17.

Awọn asọtẹlẹ Bibeli ni a ṣàkọsílẹ̀ wọn nigba ti “a ńdarí” awọn eniyan Ọlọrun “lati ọwọ́ ẹ̀mí mímọ́ [Giriiki, lati inu pneuʹma].” (2 Peteru 1:​20, 21) Ní ọ̀nà yii Bibeli ni “imisi Ọlọrun,” ọ̀rọ̀ Giriiki rẹ̀ jẹ́ The·oʹpneu·stos, tí ó tumọsi “Ọlọrun mí èémí sí.” (2 Timoti 3:16) Ẹ̀mí mímọ́ sì ṣamọna awọn eniyan kan pato lati rí awọn ìran tabi lati lá awọn àlá alasọtẹlẹ.​—⁠2 Samuẹli 23:⁠2; Joẹli 2:​28, 29; Luuku 1:67; Iṣe 1:16; 2:​32, 33.

Ẹ̀mí mímọ́ dari Jesu lati lọ sinu aginjù lẹhin iribọmi rẹ̀. (Maaku 1:12) Ẹmí naa dabii iná kan ninu awọn iranṣẹ Ọlọrun, ní mímú kí wọn ní okun-inú nipasẹ ipá yẹn. Ó sì mú kí ó ṣeeṣe fun wọn lati sọ̀rọ̀ jáde láìṣojo ati pẹlu igboya.​—⁠Mika 3:⁠8; Iṣe 7:​55-60; 18:25; Roomu 12:11; 1 Tẹsalonika 5:⁠19.

Nipasẹ ẹ̀mí rẹ̀, Ọlọrun mú awọn idajọ rẹ̀ ṣẹ lori awọn eniyan ati awọn orilẹ-ede. (Aisaya 30:​27, 28; 59:​18, 19) Ẹ̀mí Ọlọrun sì lè dé ibi gbogbo, ní gbígbé ìgbésẹ̀ fun awọn eniyan tabi lodisi wọn.​—⁠Saamu 139:​7-⁠12.

‘Agbára Tí Ó Rekọja Ti Ẹ̀dá’

Ẹ̀MÍ Ọlọrun pẹlu lè pèsè “agbára tí ó rekọja ohun tí ó jẹ ti ẹ̀dá” fun awọn tí wọn ńṣiṣẹ́ sìn ín. (2 Kọrinti 4:⁠7, NW) Eyi mú kí ó ṣeeṣe fun wọn lati faradà awọn ìdánwò igbagbọ tabi lati ṣe awọn ohun tí wọn kò lè ṣe bí kò ba jẹ́ nipa rẹ.

Fun apẹẹrẹ, nipa Samusini, Onidaajọ 14:⁠6 rohin pe: “Ẹ̀mí Yahweh si ba le e, bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pe kò ní ohun ìjà kankan ní ọwọ́ rẹ̀ ó fa kìnnìún naa ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.” (JB) Ǹjẹ́ ẹni àtọ̀runwá kan niti gidi wọnú tabi bà lé Samusini, ní dídarí ara rẹ̀ lati ṣe ohun tí ó ṣe? Bẹẹkọ, niti gidi “agbára OLUWA [ní ó] mú Samsoni lágbára.”​—⁠TEV.

Bibeli sọ pe nigba ti a baptisi Jesu, ẹ̀mí mímọ́ sọkalẹ wá sórí rẹ̀ ní fifarahan gẹgẹ bi àdàbà, kìí ṣe bíi ìrísí ẹ̀dá ènìyàn. (Maaku 1:10) Ipá agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun yii mú kí Jesu lè mú aláìsàn láradá kí ó sì jí òkú dìde. Gẹgẹ bi Luuku 5:​17 ti wi, “Agbára Oluwa [Ọlọrun] wà lẹ́hìn awọn iṣẹ́ ìmúláradá rẹ̀ [Jesu].”​—⁠JB.

Ẹ̀mí Ọlọrun tún fún awọn ọmọ-ẹhin Jesu lágbára lati ṣe awọn nǹkan yiyanilẹnu. Iṣe 2:​1-⁠4 rohin pe awọn ọmọ-ẹhin pejọ papọ̀ ní Pẹntikọsi nigba ti “lojiji ìró sì tì ọ̀run wá, gẹgẹ bi ìró ẹ̀fúùfù líle, . . . gbogbo wọn sì kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọn sì bẹ̀rẹ̀síí fi èdè miiran sọ̀rọ̀, gẹgẹ bi ẹ̀mí tí fún wọn ni ohùn.”

Nitori naa ẹ̀mí mímọ́ fún Jesu ati awọn iranṣẹ Ọlọrun miiran ní agbára lati ṣe ohun tí awọn ẹ̀dá ènìyàn lásán kò lè ṣe.

Kìí Ṣe Ẹni Kan

BÍ Ó ti wu ki o ri, awọn ẹsẹ̀ Bibeli kan kò ha wà tí wọn sọ̀rọ̀ nipa ẹ̀mí pẹlu awọn èdè ti o fihan pe o jẹ́ ẹnì kan? Bẹẹni, ṣugbọn ṣakiyesi ohun tí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Katoliki naa Edmund Fortman sọ nipa eyi ninu The Triune God: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe ẹ̀mí yii ni a saba maa nṣapejuwe pẹlu èdè jíjẹ́ ẹnì kan, ó dabii ẹni pe ó ṣe kedere pe awọn òǹkọ̀wé mímọ́ ti [Iwe Mimọ lédè Heberu] kò ronu tabi gbé ẹ̀mí mímọ́ kalẹ̀ rárá gẹgẹ bi ẹni kan tí ó dáyàtọ̀.”

Ninu Iwe Mimọ kìí ṣe ohun àràmàǹdà lati sọ awọn nǹkan alailẹmii di ẹni gidi. Ọgbọ́n ni a sọ pe ó ní awọn ọmọ. (Luuku 7:35) Ẹ̀ṣẹ̀ ati ikú ni a pè ni ọba. (Roomu 5:​14, 21) Ní Jẹnẹsisi 4:⁠7 The New English Bible (NE) sọ pe: “Ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ẹ̀mí-èṣù kan tí ó lúgọ sí ẹnu ọ̀nà,” ní pípè ẹ̀ṣẹ̀ ní ẹni gidi bii ẹ̀mí buruku kan tí ó lúgọ sí ẹnú ọ̀nà Keeni. Ṣugbọn niti tootọ, ẹ̀ṣẹ̀ kìí ṣe ẹni ẹ̀mí kan; bẹẹ sì ní sísọ ẹ̀mí mímọ́ di ẹni gidi kò sọ ọ di ẹda ẹmí kan.

Bakan naa, ní 1 Johanu 5:​6-⁠8 (NE) kìí ṣe ẹ̀mí nìkanṣoṣo ṣugbọn “omi, ati ẹ̀jẹ̀” pẹlu ni a sọ pe wọn jẹ́ “ẹlẹrii.” Ṣugbọn ó hàn gbangba pe omi ati ẹ̀jẹ̀ kìí ṣe ẹni kan, bẹẹ sì ni ẹ̀mí mímọ́ kìí ṣe ẹni kan.

Ní ìbámu pẹlu eyi ni bi Bibeli ṣe lo “ẹ̀mí mímọ́” ni gbogboogbo lọna ti ko fi i han gẹgẹ bi ẹni kan, iru bii mimu un dọgba pẹlu omi ati ina. (Matiu 3:11; Maaku 1:⁠8) Awọn eniyan ni a rọ̀ lati kún fún ẹ̀mí mímọ́ dípò kíkún fun ọtí-waini. (Efesu 5:​18) A sọ̀rọ̀ nipa wọn pe wọn kún fun ẹ̀mí mímọ́ ní ọ̀na kan naa tí wọn gbà fi kún fún iru awọn ànímọ́ bii ọgbọ́n, igbagbọ, ati ìdùnnú. (Iṣe 6:⁠3; 11:24; 13:52) Ati ní 2 Kọrinti 6:⁠6 ẹ̀mí mímọ́ wà lara iye awọn ànímọ́ kan. Iru awọn ọ̀rọ̀ bẹẹ kí yoo ti wọ́pọ̀ tobẹẹ bí ẹ̀mí mímọ́ bá jẹ́ ẹni kan niti tootọ.

Lẹhin naa, pẹlu, nigba ti awọn ọ̀rọ̀-ìwé Bibeli kan sọ pe ẹ̀mí mímọ́ a maa sọ̀rọ̀, awọn ọ̀rọ̀-ìwé miiran fihan pe eyi ni a ṣe niti tootọ nipasẹ awọn ẹ̀dá ènìyàn tabi awọn angẹli. (Matiu 10:​19, 20; Iṣe 4:​24, 25; 28:25; Heberu 2:⁠2) Ìgbéṣẹ́ ẹ̀mí ninu iru awọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹẹ dabi ti awọn ìgbì redio tí ńta awọn ìhìn-iṣẹ́ látaré lati ọ̀dọ̀ ẹni kan sí ẹlomiran ní ọ̀nà jíjìn.

Matiu 28:19 itọka ni a ṣe sí “orukọ . . . ẹ̀mí mímọ́.” Ṣugbọn ọ̀rọ̀ naa “orukọ” kìí fi igba gbogbo tumọsi orukọ ara-ẹni kan, yala ní èdè Giriiki tabi ní Gẹẹsi. Nigba ti a bá sọ pe “ní orukọ ofin,” a kò tọkasi ẹni kan. A ní ohun tí ofin naa dúró fún lọkan, agbara rẹ̀. Word Pictures in the New Testament ti Robertson sọ pe: “Ìlò orukọ (onoma) níhìn-ín jẹ́ ọ̀kan tí ó wọ́pọ̀ ninu Septuagint ati awọn papyrus fun agbára tabi àṣẹ.” Nitori naa bibaptisi ‘ní orukọ ẹ̀mí mímọ́’ jẹ mimọ agbara ẹ̀mí dájú, pe ó wá lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun tí ó sì ńṣiṣẹ́ nipasẹ ìfẹ́ inú Ọlọrun.

“Olùrànlọ́wọ́” Naa

JESU sọ̀rọ̀ nipa ẹ̀mí mímọ́ gẹgẹ bi “olùrànlọ́wọ́,” ó si sọ pe yoo kọ́ni, ṣamọna, yoo sì sọ̀rọ̀. (Johanu 14:​16, 26; 16:⁠13) Ọ̀rọ̀ Giriiki tí o lò fun olùrànlọ́wọ́ (pa·raʹkle·tos) jẹ ní ọrọ arọpo orukọ ti akọ. Nitori naa nigba ti Jesu tọkasi ohun tí olùrànlọ́wọ́ naa yoo ṣe, oun lò awọn ọ̀rọ̀ arọ́pọ̀ orúkọ tíí ṣe akọ. (Johanu 16:​7, 8) Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, nigba ti a bá lò ọ̀rọ̀ Giriiki kòṣakọ-kòṣabo fun ẹ̀mí (pneuʹma), ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ kòṣakọ-kòṣabo naa “o” ni a múlò lọna tí ó tọna.

Ọpọ julọ awọn olùtúmọ̀ ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹtalọkan fi òtítọ́ yii pamọ́, gẹgẹ bi New American Bible ti Katoliki ṣe gbà nipa Johanu 14:17 pe: Ọ̀rọ̀ Giriiki naa fun ‘Ẹ̀mí’ jẹ́ kòṣakọ-kòṣabo, ati nigba ti ó jẹ́ pe a ńlò awọn ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ ní Gẹẹsi (‘o’ [ọkunrin], ‘rẹ̀’ [ọkunrin] ‘oun’ [ọkunrin]), eyi tí ó pọ julọ lára MSS [awọn ìwé] lédè Giriiki ńṣe àmúlò ‘o.’”

Nitori naa nigba ti Bibeli lò awọn ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ ti o jẹ́ ẹni akọ ní ìsopọ̀ pẹlu pa·raʹkle·tos Johanu 16:​7, 8, ó ńbá awọn ofin ìdíwọ̀n gírámà ṣe déédéé, kìí ṣe pe ó ńṣàlàyé ẹ̀kọ́ kan.

Kìí Ṣe Apákan Mẹtalọkan

ONIRUURU awọn orísun ní o mọ̀ pe Bibeli kò ti èrò naa lẹ́hìn pe ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹni kẹta ninu Mẹtalọkan. Fun apẹẹrẹ:

The Catholic Encyclopedia: “Kò sí ibikibi ninu Majẹmu Laelae tí a ti rí itọkasi ṣiṣe kedere eyikeyii nipa Ẹni Kẹta kan.”

Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Katoliki naa Fortman: “Awọn Juu kò fìgbà kankan rí kà ẹ̀mí sí ẹni kan; bẹẹ sì ni kò sí ẹ̀rí ti o fẹsẹ̀múlẹ̀ eyikeyii pe òǹkọ̀wé Majẹmu Laelae eyikeyii di ojú ìwòye yii mú . . . Ẹ̀mí Mímọ́ ni a saba maa ngbékalẹ̀ ninu Ihinrere mẹta akọkọ ninu Majẹmu Titun [Awọn Ihinrere] ati ninu Iṣe gẹgẹ bi ipá tabi agbára àtọ̀runwá kan.”

New Catholic Encyclopedia: “Ní kedere ni M[ajẹmu] L[aelae] kò fojú inú wo ẹ̀mí Ọlọrun gẹgẹ bi ẹni kan . . . ẹ̀mí Ọlọrun wulẹ̀ jẹ́ agbára Ọlọrun. Bí a bá sọrọ rẹ nigba miiran gẹgẹ bi eyi tí ó dáyàtọ̀ sí Ọlọrun, ó jẹ nitori pe èémí Yahweh ńṣiṣẹ́ lẹhin ode ara rẹ.” Ó tún sọ pẹlu pe: “Apá ti ó pọ̀ julọ ninu awọn ọ̀rọ̀-ìwé M[ajẹmu] T[itun] ṣí ẹ̀mí Ọlọrun páya gẹgẹ bi ohun kan, kìí ṣe ẹni kan; eyi ni a rí pàápàá ninu ìdọ́gba tí ó wà laaarin ẹ̀mí ati agbára Ọlọrun.”​—⁠Ikọwe wínníwínní jẹ́ tiwa.

A Catholic Dictionary: “Bori gbogbo rẹ̀, Majẹmu Titun, gẹgẹ bi ti Laelae, sọrọ nipa ẹ̀mí naa gẹgẹ bi okun-inú tabi agbára àtọ̀runwa.”

Fun ìdí yii, kìí ṣe yálà awọn Juu tabi awọn Kristẹni ijimiji ni wọn wo ẹ̀mí mímọ́ gẹgẹ bi apákan Mẹtalọkan. Ẹ̀kọ́ yẹn jẹyọ ní ọpọlọpọ ọgọrun-un ọdun lẹhin naa. Gẹgẹ bi A Catholic Dictionary ti ṣakiyesi: “Ẹni kẹta ni a kede ní Àjọ ìgbìmọ̀ Alẹksandria ni 362 . . . ati nikẹhin nipasẹ Àjọ-ìgbìmọ̀ ti Constantinople ti 381”​—⁠nǹkan bii ọgọrun-un ọdun mẹta ati ààbọ̀ lẹhin tí ẹ̀mí mímọ́ kún awọn ọmọ-ẹhin ní Pẹntikọsi!

Bẹẹkọ, ẹ̀mí mímọ́ kìí ṣe ẹni kan kìí sìí ṣe apákan Mẹtalọkan. Ẹ̀mí mímọ́ jẹ ipá agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun tí oun ńlò lati ṣàṣeparí ìfẹ́ inú rẹ̀. Kò báramu pẹlu Ọlọrun ṣugbọn ó wà labẹ akoso rẹ̀ ó sì jẹ ọmọ-abẹ́ fun un.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]

“Bori gbogbo rẹ̀, Majẹmu Titun, gẹgẹ bi ti Laelae, sọrọ nipa ẹ̀mí naa gẹgẹ bi okun-inú tabi agbára àtọ̀runwa.”​—⁠A Catholic Dictionary

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ní àkókò kan ẹ̀mí mímọ́ farahàn gẹgẹ bi àdàbà. Ní àkókò miiran ó farahàn bíi ahọ́n iná​—⁠kìí ṣe gẹgẹ bi ẹni kan láé