Bawo Ni Wọn Ṣe Ṣàlàyé Mẹtalọkan?
Bawo Ni Wọn Ṣe Ṣàlàyé Mẹtalọkan?
ṢỌỌṢI Roman Katoliki sọ pe: “Mẹtalọkan ni èdè ìsọ̀rọ̀ ti o ṣapẹẹrẹ olori ẹ̀kọ́ isin Kristẹni . . . Nipa bayii, ninu awọn ọ̀rọ̀ Ìjẹ́wọ́ Ìgbàgbọ́ Athanasius: ‘Baba jẹ́ Ọlọrun, Ọmọkunrin jẹ́ Ọlọrun, Ẹ̀mí Mímọ́ sì jẹ́ Ọlọrun, síbẹ̀ kìí ṣe Ọlọrun mẹta ni ó wà bíkòṣe Ọlọrun kanṣoṣo.’ Ninu Mẹtalọkan yii . . . awọn ẹni wọnyi jumọ jẹ ẹni ayérayé ati ọgbọọgba: gbogbo wọn patapata jẹ́ ẹni ti a kò ṣẹ̀dá ati alágbára gbogbo.”—The Catholic Encyclopedia.
Ó fẹrẹẹ jẹ́ pe gbogbo awọn ṣọọṣi yooku ní Kristẹndọmu ni wọn fohùnṣọ̀kan pẹlu eyi. Fun apẹẹrẹ, Ṣọọṣi Greek Orthodox pẹlu pe Mẹtalọkan ní “ìpilẹ̀ ẹ̀kọ́ isin Kristẹni,” tí ó tilẹ̀ sọ pe: “Awọn Kristẹni ni awọn wọnni tí wọn tẹwọgba Kristi gẹgẹ bi Ọlọrun.” Ninu iwe naa Our Orthodox Christian Faith, ṣọọṣi kan naa polongo pe: “Ọlọrun jẹ́ mẹta ninu ọ̀kan. . . . Baba jẹ́ Ọlọrun ni gbogbo ọ̀nà. Ọmọkunrin jẹ́ Ọlọrun ni gbogbo ọ̀nà. Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ Ọlọrun ni gbogbo ọ̀nà.”
Nipa bayii, Mẹtalọkan ni a ro pe ó jẹ́ “Ọlọrun kan ninu Ẹni mẹta.” Ọ̀kọ̀ọ̀kan ni a sọ pe kò ni
ìbẹ̀rẹ̀, tí ó ti wà títí ayérayé. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ni a sọ pe ó jẹ́ alágbára ńlá gbogbo, tí ọ̀kan kò si tobi ju tabi kere ju awọn yooku lọ.Iru ironu bẹẹ ha nira lati tẹ̀lé bi? Ọpọlọpọ awọn onígbàgbọ́ olótìítọ́ inú ti ríi pe ó ńfà ìdàrúdàpọ̀, ó lodisi ironu tí ó wà déédéé, kò dabi ohunkohun tí wọn ti ní iriri rẹ̀ rí. Wọn beere pe, bawo ni Baba ṣe lè jẹ́ Ọlọrun, kí Jesu jẹ́ Ọlọrun, kí ẹmí mímọ́ sì jẹ́ Ọlọrun, síbẹ̀ kí ó má jẹ́ pe Ọlọrun mẹta ni ó wà bíkòṣe Ọlọrun kanṣoṣo?
“Ó Rekọja Ohun Tí Ironu Eniyan Lè Lóye”
ÌDÀRÚDÀPỌ̀ yii ti tànkálẹ̀. Encyclopedia Americana ṣakiyesi pe ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ni a kà sí eyi tí ó “rekọja ohun tí ironu eniyan lè lóye.”
Ọpọlọpọ tí wọn tẹwọgba Mẹtalọkan fojúwò ó ní ọ̀nà yẹn. Monsignor Eugene Clark sọ pe: “Ọ̀kan ni Ọlọrun, Ọlọrun si tun jẹ mẹta. Niwọn bi kò ti sí ohun kankan tí ó jọ eyi ninu ìṣẹ̀dá, awa kò lè lóye rẹ̀, ṣugbọn kí a kàn tẹwọgba á ni.” Cardinal John O’Connor sọ pe: “Awa mọ̀ pe ohun ìjìnlẹ̀ tí ó jinlẹ̀ gan-an ni, eyi tí awa kò tíì bẹ̀rẹ̀síí lóye rẹ.” Pope John Paul II sì sọ nipa “ohun ìjìnlẹ̀ tí ó farasin nipa Ọlọrun Mẹtalọkan naa.”
Nipa bayii, A Dictionary of Religious Knowledge sọ pe: “Ohun tí ẹ̀kọ́ naa jẹ gẹ́lẹ́, tabi bí a ó ṣe ṣalaye rẹ̀ gẹ́lẹ́, ni awọn onígbàgbọ́ Mẹtalọkan kò fohùnṣọ̀kan laaarin araawọn.”
Awa lè lóye nigba naa, ìdí tí New Catholic Encyclopedia fi ṣakiyesi pe: “Awọn olùkọ́ ẹ̀kọ́-ìsìn Mẹtalọkan kéréje ni ó wà ní awọn ilé-ẹ̀kọ́ oyè àlùfáà Roman Katoliki tí a kò tíì fi ìbéèrè pinlẹ́mìí ní akoko kan tabi omiran pe ‘Ṣugbọn bawo ni ẹnikan ṣe lè waasu Mẹtalọkan?’ Bí ibeere naa bá sì fi àmì ìdàrúdàpọ̀ hàn ní iha ọ̀dọ̀ awọn akẹ́kọ̀ọ́ naa, afaimọ ki o ma jẹ àmì iru ìdàrúdàpọ̀ bẹẹ gẹ́gẹ́ ní iha ọ̀dọ̀ awọn ọ̀jọ̀gbọ́n wọn.”
Otitọ akiyesi yẹn ni a lè jẹrii si nipa lílọ sí ibi àkójọ ìwé kíká kí a sì ṣàyẹ̀wọ̀ awọn ìwé tí wọn ti Mẹtalọkan lẹ́hìn. Àìmọye awọn oju iwe ni a ti kọ ninu igbiyanju lati ṣalaye rẹ̀. Síbẹ̀, lẹhin jíjìjàkadì lati là awọn èdè ìsọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́-ìsìn ti o lọjupọ ati awọn alaye onídàrúdàpọ̀ kọja, awọn olùwádìí kò tíì ní itẹlọrun síbẹ̀síbẹ̀.
Nipa ọ̀ràn yii, onísìn Jesuit Joseph Bracken ṣakiyesi ninu ìwé rẹ̀ What Are They Saying About the Trinity? pe: “Awọn alufaa tí wọn fi ìsapá ńláǹlà kẹ́kọ̀ọ́ . . . Mẹtalọkan nígbà awọn ọdun wọn ní ilé-ẹ̀kọ́ oyè àlùfáà maa ńlọ́tìkọ̀ lọna ti ẹ̀dá lati gbé e kalẹ̀ fun awọn eniyan wọn lati orí àga ìwàásù, kódà ní ọjọ Sunday ti a yasọtọ fun Mẹtalọkan. . . . Eeṣe tí ẹnikan fi nilati dá awọn eniyan lágara pẹlu ohun kan tí ó jẹ́ pe ní opin rẹ̀ wọn kì yoo lóye rẹ̀ lọna tí ó ṣe kedere?” Oun tun sọ pe: “Mẹtalọkan jẹ́ ẹkọ ti o wa kiki nipa orukọ, ṣugbọn agbara idari diẹ ni ó ní bí ó bá tilẹ̀ wà rárá ninu ìgbèsí-ayé ati ijọsin Kristẹni lati ọjọ́ dé ọjọ́.” Síbẹ̀, oun ni olori “ẹ̀kọ́” awọn ṣọọṣi!
Ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìsìn Katoliki naa Hans Küng ṣakiyesi ninu iwe rẹ̀ Christianity and the World Religions pe Mẹtalọkan jẹ́ ìdí kan tí kò fi rọrun fun awọn ṣọọṣi lati ṣe aṣeyọri gidi kan pẹlu awọn eniyan tí kìí ṣe Kristẹni. Oun sọ pe: “Kódà awọn Musulumi tí wọn jẹ onimọ jijinlẹ kò wulẹ̀ lè mòye rẹ̀, gẹgẹ bi awọn Juu títí di isinsinyi lọnakọna ti kùnà lati loye ẹkọ Mẹtalọkan naa. . . . Awọn ifiwera tí ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan naa ti ṣe laaarin Ọlọrun kan ati awọn ẹni mẹta naa kò tẹ́ awọn Musulumi lọ́rùn, awọn tí èdè ìsọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́-ìsìn tí o jẹyọ lati inu èdè Siria, Giriiki, ati Latini, ti ko ìdàrúdàpọ̀ ba, dípò ilaloye. Awọn Musulumi rí gbogbo rẹ̀ gẹgẹ bi fifi ọrọ ṣe arumọjẹ . . . Eeṣe tí ẹnikan fi nilati fẹ́ lati fi ohunkohun kún èròǹgbà ìjẹ́-ọ̀kanṣoṣo ati jíjẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ Ọlọrun kiki lati lú u pọ tabi sọ jìjẹ́ ọ̀kanṣoṣo ati jìjẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ yẹn dasán?”
“Kìí Ṣe Ọlọrun Ìdàrúdàpọ̀”
BAWO ni irufẹ ẹ̀kọ́ onídàrúdàpọ̀ bẹẹ ṣe pilẹ̀ṣẹ̀? The Catholic Encyclopedia sọ pe: “Ẹ̀kọ́ aláìjampata kan tí ó jẹ́ ohun ìjìnlẹ̀ tobẹẹ yẹ ki o ni iṣipaya Atọrunwa. Awọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Katoliki Karl Rahner ati Herbert Vorgrimler sọ ninu Theological Dictionary wọn pe: “Mẹtalọkan jẹ́ ohun ìjìnlẹ̀ . . . ní èrò ìtumọ̀ ti o kunrẹrẹ . . . , tí a kò lè mọ̀ láìsí ìṣípayá, àní lẹhin ìṣípayá pàápàá gbogbo rẹ̀ kò lè di eyi ti ó bọ́gbọ́nmu látòkèdelẹ̀.”
Bi o ti wu ki o rí, titẹpẹlẹ mọ ọn pe niwọn bi 1 Kọrinti 14:33, Revised Standard Version (RS).
Mẹtalọkan ti jẹ́ iru ohun ìjìnlẹ̀ bẹẹ, ó gbọdọ ti wá nipasẹ ìṣípayá àtọ̀runwá kan dá ìṣòro pàtàkì miiran sílẹ̀. Eeṣe? Nitori pe ìṣípayá àtọ̀runwá fúnraarẹ̀ kò yọnda fun irufẹ ojú ìwòye bẹẹ nipa Ọlọrun: “Ọlọrun kìí ṣe Ọlọrun ìdàrúdàpọ̀.”—Ní ojú ìwòye gbólóhùn ọ̀rọ̀ yẹn, Ọlọrun yoo ha jẹ́ okùnfà ẹ̀kọ́ kan tí ó ńfà ìdàrúdàpọ̀ nipa araarẹ tobẹẹ ti ó fi jẹ́ pe awọn ọ̀mọ̀wé Latini, Giriiki, ati Heberu kò lè ṣalaye rẹ̀ niti gidi?
Siwaju sii, awọn eniyan ha nilati jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ‘lati mọ̀ Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa ati Jesu Kristi ẹni tí oun rán’? (Johanu 17:3, JB) Bí iyẹn bá ni ọ̀ràn naa, eeṣe tí o fi jẹ kiki iwọnba diẹ ninu awọn aṣaaju isin Juu ti wọn moye ni wọn mọ Jesu dájú gẹgẹ bi Mesaya naa? Dípò bẹẹ, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ olùṣòtítọ́ jẹ́ awọn àgbẹ̀ onírẹ̀lẹ̀, awọn apẹja, awọn agbowó orí, awọn ìyàwó ilé. Awọn eniyan gbáàtúù wọnyẹn ní idaniloju ohun tí Jesu fi kọ́ wọn nipa Ọlọrun tí ó fi jẹ́ pe wọn lè fi kọ́ awọn ẹlomiran tí wọn tilẹ̀ múratán lati kú nitori ìgbàgbọ́ wọn.—Matiu 15:1-9; 21:23-32, 43; 23:13-36; Johanu 7:45-49; Iṣe 4:13.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Awọn ọmọ-ẹhin Jesu jẹ́ awọn eniyan gbáàtúù rírẹlẹ̀, kìí ṣe awọn aṣaaju isin