Igba Gbogbo Ha Ni Ọlọrun Ga Lọ́lá Jù Jesu Bí?
Igba Gbogbo Ha Ni Ọlọrun Ga Lọ́lá Jù Jesu Bí?
JESU kò sọ láé pe oun jẹ́ Ọlọrun. Gbogbo ohun tí oun sọ nipa araarẹ̀ fihan pe oun kò kà araarẹ̀ si ọgbọọgba pẹlu Ọlọrun lọnakọna—kìí ṣe ninu agbára, ní ìmọ̀, tabi ní ọjọ́ orí.
Ní gbogbo akoko wíwà rẹ̀, yálà ní ọ̀run tabi lori ilẹ̀-ayé, ọ̀rọ̀ sísọ ati ìwà rẹ̀ fi i hàn gẹgẹ bi òṣìṣẹ́ ọmọ-abẹ́ fun Ọlọrun. Ọlọrun ga lọ́lá jù nigba gbogbo, Jesu ẹni ti o rẹ̀lẹ̀ jù ni Ọlọrun ṣẹ̀dá.
A Fìyàsọ́tọ̀ Sí Jesu ati Ọlọrun
NÍ Ọ̀PỌ̀ ìgbà, Jesu fihan pe oun jẹ́ ìṣẹ̀dá kan tí ó yàtọ̀ sí Ọlọrun ati pe oun, Jesu, ní Ọlọrun kan tí ó ga jù oun lọ, Ọlọrun kan tí oun ńjọ́sìn, Ọlọrun kan tí oun pè ní “Baba.” Ninu adura sí Ọlọrun, eyiini ni, Baba, Jesu sọ pe, “Iwọ, nìkan Ọlọrun otitọ.” (Johanu 17:3) Ní Johanu 20:17 oun sọ fun Maria Magidaleni pe: “Emi ńgòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi, ati Baba yin; ati sọ́dọ̀ Ọlọrun mi, ati Ọlọrun yin.” (RS, ẹ̀dà ti Katoliki) Ní 2 Kọrinti 1:3 apọsiteli Pọọlu tubọ fìdí ipò ìbátan yii múlẹ̀ pe: “Olubukun ni Ọlọrun, ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa.” Niwọn bi Jesu ti ní Ọlọrun kan, Baba rẹ̀, nigba kan naa, oun kò lè jẹ́ Ọlọrun yẹn.
Apọsiteli Pọọlu kò ní iyèméjì kankan ni sísọ̀rọ̀ nipa Jesu ati Ọlọrun pe wọn yàtọ̀ gidigidi: “Fun awa Ọlọrun kan ni ńbẹ̀, Baba, . . . Oluwa kan sì ni ńbẹ, Jesu Kristi.” (1 Kọrinti 8:6, JB) Apọsiteli naa fi ìyàtọ naa hàn nigba ti ó sọ pe “niwaju Ọlọrun ati ti Kristi Jesu ati ti awọn angẹli ààyò àyànfẹ́.” (1 Timoti 5:21, RS Common Bible) Gan-an gẹgẹ bi Pọọlu ti sọ nipa Jesu ati awọn angẹli pe wọn yàtọ̀ sí araawọn ẹnikinni keji ní ọ̀run, bẹẹ gẹ́gẹ́ ni ó jẹ́ niti Jesu ati Ọlọrun.
Awọn ọ̀rọ̀ Jesu ní Johanu 8:17, 18 ṣe pàtàkì pẹlu. O sọ pe: “Ẹ sì kọ́ ọ pẹlu ninu ofin yin pe, otitọ ní ẹ̀rí eniyan meji. Emi ni ẹni tí ńjẹ́rìí araami, ati Baba tí ó rán mi sì ńjẹ́rìí fun mi.” Níhìn-ín Jesu fihan pe oun ati Baba rẹ̀, eyiini ni, Ọlọrun Olodumare, gbọdọ jẹ́ awọn ẹda ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ meji, nitori pe ọ̀nà wo tún ni awọn ẹlẹrii meji ṣè lè wà nitootọ?
Jesu fihan siwaju sii pe oun jẹ́ ẹda ti o yatọ kan si Ọlọrun nipa sísọ pe: “Eeṣe ti iwọ fi pè mi ni ẹni daradara? Ẹni daradara kan kò sí àfi Ọlọrun nìkanṣoṣo.” (Maaku 10:18, JB) Nihin-in Jesu ńsọ pe kò sí ẹni tí ó dara bii ti Ọlọrun, àní kìí ṣe Jesu fúnraarẹ̀ pàápàá. Ọlọrun dara ní ọ̀nà kan tí ó mu ki o yàtọ̀ sí Jesu.
Iranṣẹ Ọlọrun Olutẹriba
NÍ ỌPỌ igba leralera, Jesu sọ awọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ iru bii: “Ọmọkunrin kò lè ṣe ohunkohun bí ó ti wù ú, ohun tí ó bá rí ti Baba rẹ̀ ńṣe nìkanṣoṣo ni ó lè ṣe.” (Johanu 5:19, The Holy Bible, lati ọwọ́ Monsignor R. A. Knox) “Mo ti sọ̀kalẹ̀ wá lati ọ̀run lati ṣe, kìí ṣe ìfẹ́ inú mi, bíkòṣe ìfẹ́ inú ẹni naa tí ó rán mi.” (Johanu 6:38, NW) “Ohun tí mo fi ńkọ́ni kìí ṣe tèmi, ṣugbọn ó jẹ́ ti ẹni naa tí ó rán mi.” (Johanu 7:16, NW) Ẹni ti o ranni kò ha ga lọ́lá jù ẹni tí a rán bi?
Ipò ìbátan yii ṣe kedere ninu àkàwé Jesu nipa ọgbà àjàrà. Oun fi Ọlọrun, Baba rẹ̀, wé ẹni ti o ni ọgbà àjàrà, tí ó rinrin ajo tí ó sì fi ọgba ajara naa sílẹ̀ sí àbójútó awọn aroko, tí wọn dúró fún àwùjọ awọn àlùfáà Juu. Nigba ti oní nǹkan rán ẹrú kan lọ lẹhin naa lati já diẹ lára èso ọgbà àjàrà naa, awọn aroko lù ẹrú naa wọn sì rán an lọ lọ́wọ́ òfo. Lẹhin naa oní-nǹkan rán ẹrú keji, ati nigba ti ó yá ẹkẹta, tí awọn mejeeji si rí ìhùwàsí kan naa gbà. Níkẹhìn oní nǹkan naa sọ pe: “Emi yoo rán ọmọ [ọmọkunrin] mi [Jesu] àyànfẹ́ lọ: bóyá nigba ti wọn bá rí i wọn yoo ṣe ojúsàájú fun un.” Ṣugbọn awọn aroko tí a ti sọ dìbàjẹ́ naa sọ pe: “‘Eyi ni àrólé: ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún rẹ̀ kí ó lè jẹ́ tiwa.’ Bẹẹni wọn sì tì í jáde sẹhin ọgbà-àjàrà wọn sì pa á.” (Luuku 20:9-16) Nipa bayii, Jesu ṣàkàwé ipò rẹ̀ gẹgẹ bi ẹni kan tí Ọlọrun rán lati ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun, gan-an gẹgẹ bi baba kan ṣe rán ọmọkunrin rẹ̀ olùtẹríba.
Awọn ọmọlẹhin Jesu maa ńwò ó nigba gbogbo gẹgẹ bi iranṣẹ Ọlọrun olùtẹríba, kìí ṣe gẹgẹ Iṣe 4:23, 27, 30, RS, ẹ̀dà Katoliki.
bi alábàádọ́gba rẹ̀. Wọn gbadura sí Ọlọrun nipa “Jesu iranṣẹ rẹ mímọ́, ẹni tí iwọ fi òróró yàn, . . . awọn àmì ati awọn ohun ìyanu ni a múṣe nipasẹ orukọ iranṣẹ rẹ mímọ́ Jesu.”—Ọlọrun Ga Lọlá Jù Ní Gbogbo Ìgbà
NÍ ÌBẸ̀RẸ̀ iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu gan-an, nigba ti ó jade wá lati inu omi baptism, ohùn Ọlọrun lati ọ̀run sọ pe: “Eyi ni Ọmọkunrin mi, ààyò olùfẹ́, ẹni tí mo ti tẹwọ́gbà.” (Matiu 3:16, 17, NW) Ọlọrun ha ńsọ pe oun ni ọmọkunrin oun funra oun, pe oun tẹ́wọ́gbà ara oun, pe oun rán ara oun? Bẹẹkọ, Ọlọrun Ẹlẹdaa sọ pe oun, gẹgẹ bi ẹni gíga lọ́lá jù, tẹ́wọ́gbà ẹni kíkéré jù, Ọmọkunrin rẹ̀ Jesu, fun iṣẹ́ tí ó wà níwájú.
Jesu fi gíga lọ́lá jù Baba rẹ̀ hàn nigba ti ó sọ pe: “Ẹ̀mí Oluwa [“Jehofa,” NW] ńbẹ lára mi, nitori ti ó fi àmì-òróró yàn mi lati waasu ihinrere fun awọn òtòṣì.” (Luuku 4:18) Ìfòróróyàn jẹ́ fifunni ni agbara tabi àṣẹ kan lati ọwọ́ ẹni gíga lọ́lá jù fun ẹnikan tí ko ní àṣẹ tẹ́lẹ̀. Níhìn-ín Ọlọrun ni o ga lọ́lá jù lọna tí ó hàn gbangba, nitori pe oun fòróróyàn Jesu, ní fifun un ní agbara tí oun kò ní ṣaaju.
Jesu mú ìgalọ́lájù Baba rẹ̀ ṣe kedere nigba ti ìyá awọn ọmọ-ẹhin meji beere pe kí awọn ọmọkunrin rẹ̀ jokoo ọ̀kan ní ọ̀tún ati ọ̀kan ní òsì Jesu nigba ti oun bá dé sinu Ijọba rẹ̀. Jesu dahun pe: “Niti awọn ijokoo ní ọwọ́ ọ̀tún mi ati òsì mi, iwọnyi kìí ṣe tèmi lati fifunni; wọn jẹ́ ti awọn wọnni tí a ti yàn án fún lati ọ̀dọ̀ Baba mi,” eyiini ni, Ọlọrun. (Matiu 20:23, JB) Ìbá jẹ́ pe Jesu Kristi ti jẹ́ Ọlọrun Olodumare, awọn àyè wọnyi ni ìbá ti jẹ́ tirẹ̀ lati fifunni. Ṣugbọn Jesu kò lè fifun wọn nitori pe ti Ọlọrun ni lati fifunni, Jesu kìí sìí ṣe Ọlọrun.
Awọn adura Jesu fúnraarẹ̀ jẹ́ apẹẹrẹ alágbára ti ipò rẹ̀ tí ó rẹlẹ̀. Nigba ti ó kú diẹ kí Jesu kú, o fi ẹni tí ó ga lọ́lá jù hàn nipa gbígbàdúrà pe: “Baba, bí iwọ bá fẹ́, gbà ago yii lọwọ mi: ṣugbọn ìfẹ́ ti emi kọ́, bíkòṣe tìrẹ ni kí a ṣe.” (Luuku 22:42) Ta ni oun ńgbàdúrà sí? Ṣe sí apákan araarẹ̀ ni bi? Bẹẹkọ, oun ńgbàdúrà sí ẹni kan tí ó yàtọ̀ patapata, Baba rẹ̀, Ọlọrun, ẹni tí ìfẹ́ inú rẹ̀ ga lọ́lá jù tí ó si lè yàtọ sí tirẹ̀, Ẹni kanṣoṣo tí ó lágbára lati “gbà ago yii.”
Lẹhin naa, bí ó ti ndé ojú ikú, Jesu kígbe jade pe: “Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, eeṣe tí iwọ fi kọ̀ mi tì?” (Maaku 15:34, JB) Ta ni Jesu ńkígbe jade sí? Ṣe araarẹ̀ tabi sí apákan araarẹ̀ ni bi? Dajudaju igbe yẹn, “Ọlọrun mi,” kìí ṣe lati ọ̀dọ̀ ẹni kan tí ó ka araarẹ̀ sí Ọlọrun. Bí Jesu bá si jẹ́ Ọlọrun, nigba naa ta ni ó kọ̀ ọ́ tì? Ṣe oun fúnraarẹ̀ ni? Iyẹn kì yoo bá ọgbọ́n mu. Jesu tún sọ pe: “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.” (Luuku 23:46) Bí Jesu bá jẹ́ Ọlọrun, fun ìdí wo ni oun yoo fi nilati fi ẹ̀mí rẹ̀ síkàáwọ́ Baba?
Lẹhin tí Jesu kú, oun wà ninu ibojì fun apákan ọjọ́ mẹta. Bí oun bá jẹ́ Ọlọrun, nigba naa Habakuku 1:12 (NW), kò tọ̀nà nigba ti o sọ pe: “Óò Ọlọrun mi, Ẹni Mímọ́ mi, iwọ kìí kú.” Ṣugbọn Bibeli sọ pe Jesu kú niti gidi ó sì wà laimọ ohunkohun ninu ibojì. Ta ni ó jí Jesu dìde kuro ninu òkú? Bí oun bá kú nitootọ, oun ki ba ti lè jí araarẹ̀ dìde. Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, bí oun kò bá kú niti gidi, ikú ìdíbọ́n rẹ̀ kì yoo ti san iye-owó ìràpadà fun ẹ̀ṣẹ̀ Adamu. Ṣugbọn oun san iye-owó yẹn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nipasẹ ojúlówó ikú rẹ̀. Nitori naa “Ọlọrun [ni ẹni tí ó] jí [Jesu] dìde nipa títú ìdè ìroragógó ikú.” (Iṣe 2:24, NW) Ẹni gíga lọ́lá jùlọ naa, Ọlọrun Olodumare jí ẹni rírẹlẹ̀ jù, Jesu iranṣẹ rẹ, dìde kuro ninu òkú.
Ǹjẹ́ agbara Jesu lati ṣe awọn iṣẹ́-ìyanu, iru bii jíjí oku dìde, fihan pe oun jẹ́ Ọlọrun bi? Tóò, awọn apọsiteli ati wolii Elija ati Eliṣa ní agbára yẹn pẹlu, ṣugbọn iyẹn kò mú wọn jù awọn eniyan yooku lọ. Ọlọrun fi agbara lati ṣe awọn iṣẹ iyanu fún awọn wolii, Jesu, ati awọn apọsiteli
rẹ lati fihan pe Oun ńtì wọn lẹ́hìn. Ṣugbọn kò sọ ọ̀kankan wọn di apákan Ọlọrun ẹlẹni mẹ́ta ẹlẹni pupọ.Jesu Ní Ìmọ̀ Tí Ó Láàlà
NIGBA ti Jesu funni ni asọtẹlẹ rẹ̀ nipa opin ètò ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii, oun sọ pe: “Ṣugbọn niti ọjọ́ yẹn tabi wákàtí yẹn ẹnikankan kò mọ̀ ọ́n, àní kìí tilẹ̀ ṣe awọn angẹli ní ọ̀run, tabi Ọmọkunrin, bíkòṣe kìkì Baba nìkanṣoṣo.” (Maaku 13:32, RS, ẹ̀dà Katoliki) Ìbá jẹ́ pe Jesu ti jẹ́ Ọmọkunrin abaradọgba apákan Ọlọrun ẹlẹni mẹ́ta, oun ìbá ti mọ̀ ohun tí Baba rẹ̀ mọ̀. Ṣugbọn Jesu kò mọ̀, nitori pe oun kò bá Ọlọrun dọ́gba.
Bakan naa bẹẹ gẹ́gẹ́, a kà ní Heberu 5:8 pe Jesu “kọ́ igbọran nipa ohun tí ó jìyà.” A ha lè finu wòye pe Ọlọrun nilati kẹ́kọ̀ọ́ ohunkohun? Bẹẹkọ, ṣugbọn Jesu ṣe bẹẹ, nitori pe oun kò mọ ohun gbogbo tí Ọlọrun mọ̀. Oun sì nilati kẹ́kọ̀ọ́ ohun kan tí Ọlọrun kò ní kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láé—igbọran. Ọlọrun kò nilati gbọ́ràn sí ẹnikẹni láéláé.
Ìyàtọ̀ tí ó wà laaarin ohun tí Ọlọrun mọ̀ ati ohun tí Kristi mọ̀ tun wà pẹlu nigba ti a jí Jesu dìde lọ sí ọ̀run lati wà pẹlu Ọlọrun. Ṣakiyesi awọn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ iwe tí ó kẹhin Bibeli: “Iṣipaya Jesu Kristi tí Ọlọrun fifun un.” (Iṣipaya 1:1, RS, ẹ̀dà Katoliki) Bí Jesu fúnraarẹ̀ bá jẹ́ apákan Ọlọrun ẹlẹni mẹ́ta, a ha nilati fun un ní ìṣípayá kan lati ọwọ apá miiran lára Ọlọrun ẹlẹni mẹ́ta naa—Ọlọrun? Dajudaju oun ìbá ti mọ̀ ohun gbogbo nipa rẹ̀, nitori Ọlọrun mọ̀ ọ́n. Ṣugbọn Jesu kò mọ̀ ọn, nitori pe oun kìí ṣe Ọlọrun.
Jesu Nbaa Lọ Gẹgẹ bi Òṣìṣẹ́ Ọmọ-abẹ́
ṢAAJU wíwà rẹ̀ gẹgẹ bi ẹ̀dá ènìyàn, ati pẹlu nigba ti ó wà lori ilẹ̀-ayé, Jesu jẹ́ òṣìṣẹ́ ọmọ-abẹ́ fun Ọlọrun. Lẹhin tí a jí i dìde, oun nbaa lọ lati wà ní ipò òṣìṣẹ́ ọmọ-abẹ́, ipò-àyè onípòkejì.
Ní sísọ̀rọ̀ nipa ajinde Jesu, Peteru ati awọn wọnni tí wọn wà pẹlu rẹ̀ sọ fun Sanhẹdirini ti Juu pe: “Oun [Jesu] ni Ọlọrun fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbéga.” (Iṣe 5:31) Pọọlu sọ pe: “Ọlọrun pẹlu sì ti gbé e ga gidigidi.” (Filipi 2:9) Bí Jesu bá ti jẹ́ Ọlọrun, bawo ni a ṣe lè ti gbé Jesu ga, eyiini ni, kí a gbé e ga jù ipo tí ó ti gbadun ṣáájú? Oun yoo ti jẹ́ apákan tí a gbéga ninu Mẹtalọkan. Bí ó bá jẹ́ pe, ṣaaju ìgbéga rẹ̀, Jesu ti dọ́gba pẹlu Ọlọrun, gbígbé e ga sókè siwaju sii lọnakọna yoo ti mú kí ó ga lọ́lá jù Ọlọrun lọ.
Pọọlu tún sọ pe “Kristi wọ ọ̀run fúnraarẹ̀, kí oun baà lè farahan ní iwájú Ọlọrun gan-an nitori wa.” (Heberu 9:24, JB) Bí iwọ bá farahan ní iwájú ẹlomiran, bawo ni iwọ ṣe lè jẹ́ ẹni yẹn? Iwọ kò lè jẹ́ bẹẹ. Iwọ gbọdọ yàtọ̀ kí ó sì jẹ ẹni ọ̀tọ̀.
Bakan naa, gẹ́lẹ́ ṣaaju kí a tó sọ ọ ní okuta pá, ajẹ́rìíkú naa Stefanu “tẹjúmọ́ ọ̀run, ó sì rí ògo Ọlọrun, ati Jesu ńdúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun.” (Iṣe 7:55) Ní kedere, oun rí awọn ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ meji—ṣugbọn kò sí ẹ̀mí mímọ́ níbẹ̀, kò sí Mẹtalọkan Ọlọrun ẹlẹni mẹ́ta.
Ninu àkọsílẹ̀ Iṣipaya 4:8 sí 5:7, Ọlọrun ni a fihan pe ó jokoo lori ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run, ṣugbọn Jesu kò ṣe bẹẹ. Oun nilati tọ̀ Ọlọrun lọ lati gbà àkájọ ìwé ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun. Eyi fihan pe ní ọ̀run Jesu kìí ṣe Ọlọrun ṣugbọn ó yàtọ̀ sí i.
Ní ìfohùnṣọ̀kan pẹlu ohun tí a ti ńbá bọ̀, iwe naa Bulletin of the John Rylands Library ní Manchester, England, sọ pe: “Ninu iwalaaye rẹ̀ ti ọ̀run lẹhin ajinde, Jesu ni a ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹni ti ó ṣì pa jìjẹ́ ti o jẹ ẹnìkan mọ́ gẹgẹ bi ẹni ọ̀tọ̀, ti o si yatọ ni gbogbo ọna si Ọlọrun gẹgẹ bi o ṣe rí fun un nigba iwalaaye rẹ̀ lori ilẹ̀-ayé gẹgẹ bi Jesu tí ó rìn lórí ilẹ̀. Ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu Ọlọrun ati ni ifiwera pẹlu Ọlọrun, oun, nitootọ, farahan, gẹgẹ bi ẹda ti ọ̀run miiran ní ìgà ọ̀run ti Ọlọrun, gan-an gẹgẹ bi awọn angẹli ti jẹ́—bi o tilẹ̀ jẹ́ pe gẹgẹ bi Ọmọkunrin Ọlọrun, oun dúró ní ìsọ́wọ́ kan tí ó yàtọ̀, tí ó sì wà ni ipò tí ó fi jàn-ànrànjan-anran ga jù tiwọn lọ.”—Fiwe Filipi 2:11.
Bulletin tún sọ pe: “Bí o ti wu ki o ri, ohun tí a sọ nipa ìgbésí-ayé rẹ̀ ati awọn ojuṣe rẹ̀ gẹgẹ bi Kristi ti òkè-ọ̀run kò tumọsi bẹẹ sì ni kò tọka si i pe ninu ipò rẹ̀ ti ọ̀run oun dúró ní ipele dídọ́gba pẹlu Ọlọrun fúnraarẹ̀ ki o sì jẹ́ Ọlọrun lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Ní odikeji gan-an, ninu àwòrán jíjẹ́ ẹni ti ọ̀run ati iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ tí ó wà ninu Majẹmu Titun a rí ìrísí kan tí ó yàtọ̀ tí ó sì jẹ́ òṣìṣẹ́ ọmọ-abẹ́ fun Ọlọrun.”
Ní ẹ̀hìn-ọ̀la ainipẹkun ní ọ̀run, Jesu yoo maa ba a lọ lati jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀, iranṣẹ Ọlọrun tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ 1 Kọrinti 15:24, 28, NJB.
ọmọ-abẹ́. Bibeli ṣalaye rẹ̀ ní ọ̀nà yii pe: “Lẹhin iyẹn ni opin naa yoo dé, nigba ti oun [Jesu ní ọ̀run] yoo fà ijọba naa lé Ọlọrun Baba lọ́wọ́ . . . Lẹhin naa Ọmọkunrin fúnraarẹ̀ yoo wá jẹ́ ọmọ-abẹ́ Ẹni naa tí ó ti fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, kí Ọlọrun baà lè jẹ́ ohun gbogbo ninu ohun gbogbo.”—Jesu Kò sọ Pe Oun Jẹ́ Ọlọrun Nígbà Kankan Rí
IDURO Bibeli ṣe kedere. Kìí ṣe kìkì pe Ọlọrun Olodumare, Jehofa, jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀ sí Jesu ṣugbọn Oun nigba gbogbo ga lọ́lá jù ú lọ. Nigba gbogbo ni a nfi Jesu hàn gẹgẹ bi ẹni ọ̀tọ̀ tí ó rẹlẹ̀ jù, iranṣẹ onírẹlẹ̀ fun Ọlọrun. Ìdí niyẹn tí Bibeli fi sọ lọna hihan kedere pe “orí Kristi . . . ni Ọlọrun” lọna kan naa tí ó fi jẹ́ pe “Kristi ni orí olukuluku ọkunrin.” (1 Kọrinti 11:3) Ìdí sì niyẹn tí Jesu fúnraarẹ̀ fi sọ pe: “Baba tobi ju mi lọ.”—Johanu 14:28, RS, ẹ̀dà Katoliki).
Òtítọ́ naa ni pe Jesu kìí ṣe Ọlọrun kò sì sọ pe oun jẹ́ bẹẹ nígbà kankan rí. Eyi ni iye awọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ tí npọ sii ti mọ̀ dajú. Gẹgẹ bi Bulletin ti Rylands ti sọ pe: “Òtítọ́ naa ni a nilati dojúkọ pe ìwádìí ninu Majẹmu Titun, kí a sọ pe, lati ọgbọ̀n tabi ogoji ọdun sẹhin wá ti ṣamọna iye awọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ olokiki nipa Majẹmu Titun ti npọ sii lati de ori ipinnu naa pe Jesu . . . dajudaju kò gbà araarẹ̀ gbọ́ láé pe oun jẹ́ Ọlọrun.”
Bulletin naa tún sọ nipa awọn Kristẹni ọgọrun-un ọdun kìn-ínní pẹlu pe: “Nitori naa, nigba ti wọn ba fun [Jesu] ni iru awọn orúkọ oyè ti nbọlá fúnni iru bii Kristi, Ọmọkunrin eniyan, Ọmọkunrin Ọlọrun ati Oluwa, iwọnyi ni awọn ọ̀nà fun sísọ pe oun kìí ṣe Ọlọrun, bíkòṣe pe oun ṣe iṣẹ́ Ọlọrun.”
Fun ìdí yii, kódà awọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ isin kan gbà pe èrò naa pe Jesu jẹ́ Ọlọrun tako ẹri gbogbo Bibeli pata. Níbẹ̀, igba gbogbo ní Ọlọrun ga lọ́lá jù, Jesu sì jẹ́ iranṣẹ òṣìṣẹ́ ọmọ-abẹ́.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]
‘Ìwádìí ninu Majẹmu Titun ti ṣamọna iye awọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ olokiki ti npọ sii lati de ori ipinnu naa pe Jesu dajudaju kò gbà araarẹ̀ gbọ́ láé pe oun jẹ́ Ọlọrun.’—Bulletin of the John Rylands Library
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Jesu sọ fun awọn Juu pe: “Mo ti sọ̀kalẹ̀ wá lati ọ̀run lati ṣe, kìí ṣe ìfẹ́ inú mi, bíkòṣe ìfẹ́ inú ẹni naa tí ó rań mi.”—Johanu 6:38, NW
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Nigba ti Jesu kígbe jáde pe: “Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, eeṣe tí iwọ fi kọ̀ mi tì?” oun dajudaju kò gbàgbọ́ pe oun fúnraarẹ jẹ́ Ọlọrun