Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iwọ Ha Nilati Gbà Á Gbọ́ Bí?

Iwọ Ha Nilati Gbà Á Gbọ́ Bí?

Iwọ Ha Nilati Gbà Á Gbọ́ Bí?

IWỌ ha gbàgbọ́ ninu Mẹtalọkan bí? Ọpọ julọ awọn eniyan ninu Kristẹndọmu ni wọn ṣe bẹẹ. Ó ṣetán, ó ti jẹ́ olórí ẹ̀kọ́ awọn ṣọọṣi fun ọpọlọpọ ọgọrun-un ọdun.

Lójú ìwòye eyi, iwọ yoo ronu pe kò lè sí ibeere kankan nipa rẹ̀. Ṣugbọn ó wà, ati láìpẹ́ yii àní diẹ lara awọn alátìlẹ́hìn rẹ̀ ti dakun àríyànjiyàn naa.

Eeṣe tí ẹkọ bí iru eyi fi nilati ju ohun ti a le gboju foda? Nitori Jesu funraarẹ̀ sọ pe: “Ìyè ayérayé ni eyi: lati mọ̀ ọ́, iwọ Ọlọrun otitọ kanṣoṣo naa, ati Jesu Kristi ẹni tí iwọ ti rán.” Nitori naa ọjọ ọ̀la wa latokedelẹ sinmi lórí mímọ̀ tí a mọ̀ bí Ọlọrun ti jẹ́ nitootọ, tí iyẹn sì tumọsi wíwa gbongbo àríyànjiyàn nipa Mẹtalọkan. Nitori naa, eeṣe tí iwọ kò fi ṣàyẹ̀wò rẹ̀ funraarẹ?​—⁠Johanu 17:⁠3, Jerusalem Bible (JB) ti Katoliki.

Oniruuru èrò nipa Mẹtalọkan ni o wà. Ṣugbọn ní gbogbogboo ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ni pe ninu Ọlọrun ẹlẹni mẹta, awọn ẹni mẹta ni wọn wà níbẹ̀, Baba, Ọmọkunrin, ati Ẹ̀mí Mímọ̀; síbẹ̀, lápapọ̀ Ọlọrun kan ni wọn. Ẹ̀kọ́ naa sọ pe awọn mẹta naa jẹ́ ọgbọọgba, Olodumare, a kò sì ṣẹ̀dá wọn, niwọn bi wọn ti wà títíláé ninu Ọlọrun ẹni mẹta.

Awọn miiran, bi o ti wu ki o ri, sọ pe ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan jẹ́ èké, pe Ọlọrun Olodumare duro ni oun nìkanṣoṣo gẹgẹ bi ẹni ọ̀tọ̀ kan, tí ó wà títí-ayé, ti o si jẹ alágbára gbogbo. Wọn sọ pe Jesu ṣaaju wíwà rẹ̀ gẹgẹ bi ẹ̀dá ènìyàn, dabii awọn angẹli, ẹ̀dá ẹ̀mí ọ̀tọ̀ kan tí Ọlọrun dá, ati fún ìdí yii oun ti nilati ní ìbẹ̀rẹ̀ kan. Wọn ńfi kọ́ni pe Jesu kò tíì fi igba kankan dọgba pẹlu Ọlọrun Olodumare ní ìtumọ̀ eyikeyii; igbagbogbo ni oun ti wà lábẹ́ Ọlọrun ó sì tún ṣì wa bẹẹ. Wọn tun gbàgbọ́ pe ẹ̀mí mímọ́ kìí ṣe ẹda kan bíkòṣe ẹ̀mí Ọlọrun, ipá agbékánkánṣiṣẹ́ rẹ̀.

Awọn alátìlẹ́hìn Mẹtalọkan sọ pe a pilẹ̀ rẹ̀ kìí ṣe kìkì lori awọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ìsìn ṣugbọn lori Bibeli pẹlu. Awọn alatako ẹ̀kọ́ naa sọ pe kìí ṣe ẹ̀kọ́ Bibeli, orísun ìtàn kan tilẹ̀ polongo pe: “Ipilẹṣẹ [Mẹtalọkan] jẹ́ ti olórìṣà patapata.”​—⁠The Paganism in Our Christianity.

Bí Mẹtalọkan bá jẹ́ ootọ, ó rẹ̀ Jesu nípò wálẹ̀ lati sọ pe oun ko fi igba kan dọ́gba pẹlu Ọlọrun gẹgẹ bi apákan Ọlọrun ẹlẹni mẹta. Ṣugbọn bí Mẹtalọkan bá jẹ́ èké ó rẹ̀ Ọlọrun Olodumare nípò wálẹ̀ lati pe ẹnikẹni ní ọgbọọgba pẹlu rẹ̀, eyi tí ó tilẹ̀ tun buru julọ ni lati pe Maria ní “Ìyá Ọlọrun.” Bí Mẹtalọkan bá jẹ́ èké, ó tàbùkù sí Ọlọrun lati sọ gẹgẹ bi iwe naa Catholicism ti ṣakiyesi pe: “Lai jẹ pe [awọn eniyan] bá pa Igbagbọ yii mọ́ lodidi laisọ́ ọ di ẹ̀gbin, laisi iyemeji [wọn] yoo ṣègbè títíláé. Igbagbọ Katoliki si ni eyi: a njọsin Ọlọrun kan ninu Mẹtalọkan.”

Awọn ìdí rere wà nigba naa, tí iwọ yoo fi fẹ́ lati mọ otitọ nipa Mẹtalọkan. Ṣugbọn ṣaaju ṣíṣàyẹ̀wò orísun rẹ̀ ati ijẹwọ rẹ̀ pe oun jẹ otitọ, yoo ṣeranlọwọ lati tumọ ẹ̀kọ́ yii lọna tí ó tubọ ṣe pàtó. Ki ni Mẹtalọkan naa, niti gidi gan-an? Bawo ni awọn alátìlẹ́hìn rẹ̀ ṣe ṣàlàyé rẹ̀?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 2]

Òsì: Ère Ijibiti ti ẹgbẹ̀rún ọdun keji (B.C.E.) ọlọrun mẹta ti Amon-Ra, Ramses II, ati Mut. Ọ̀tún: Ère Mẹtalọkan ti Jesu Kristi, Baba, ati ẹ̀mí mímọ́ ọgọrun-un ọdun kẹrinla (C.E.). Ṣakiyesi pe ẹni mẹta ni ṣugbọn kìkì ẹsẹ̀ mẹrin.