Jọsin Ọlọrun Lori Awọn Ipo Ti Oun Fi Lelẹ
Jọsin Ọlọrun Lori Awọn Ipo Ti Oun Fi Lelẹ
JESU sọ ninu adura sí Ọlọrun pe: “Eyi tumọsi iye ainipẹkun, gbígbà tí wọn gbà ìmọ̀ iwọ, Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa sọ́kàn, ati ti ẹni naa tí iwọ rán, Jesu Kristi.” (Johanu 17:3, NW) Irú ìmọ̀ wo? “Ìfẹ́ inú [Ọlọrun] ni pe kí a gbà gbogbo oríṣi eniyan là kí wọn sì wá sinu ìmọ̀ pípéyé ti otitọ.” (1 Timoti 2:4, NW) The Amplified Bible ṣètumọ̀ ọ̀rọ̀ kukuru tí ó kẹ́hìn naa ní ọ̀nà yii pe: “Mọ̀ Otitọ [àtọ̀runwa] naa ní ẹkunrẹrẹ ati lọna tí ó jánà.”
Eyi tumọsi pe Ọlọrun ńfẹ́ kí a mọ̀ oun ati awọn ète rẹ̀ lọna pípéyé, ní ìbámu pẹlu otitọ àtọ̀runwá. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli Mímọ́, sì ni orísun otitọ yẹn. (Johanu 17:17; 2 Timoti 3:16, 17) Nigba ti awọn eniyan bá mọ̀ ohun tí Bibeli sọ nipa Ọlọrun lọna pípéye, nigba naa wọn yoo yẹra fun dídàbí awọn wọnni tí a mẹnukan ní Roomu 10:2, 3, tí wọn ní ‘ìtara fun Ọlọrun; ṣugbọn kìí ṣe gẹgẹ bi ìmọ̀.’ Tabi gẹgẹ bi awọn ará Samaria, awọn tí Jesu sọ nipa wọn pe: “Ẹyin ńjọ́sìn ohun tí ẹyin kò mọ̀.”—Johanu 4:22, NW.
Nitori naa, bí a bá ńfẹ́ ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun, ó jẹ ọ̀ranyàn fun wa lati beere lọwọ araawa pe: Ki ni Ọlọrun sọ nipa araarẹ̀? Bawo ni oun ṣe fẹ́ kí a jọsin oun? Ki ni awọn ète rẹ̀, bawo sì ni a ṣe le mu ara wa bá wọn mu? Ìmọ̀ otitọ ti o peye fun wa ní awọn idahun títọ́ sí iru awọn ibeere bẹẹ. Nigba naa a lè jọsin Ọlọrun lori awọn ipo ti oun ti fi lelẹ.
Títàbùkù Sí Ọlọrun
“AWỌN tí ó bọlá fún mi ni emi yoo bọlá fún,” ni Ọlọrun wi. (1 Samuẹli 2:30) Ó ha bọlá fún Ọlọrun lati pè ẹnikẹni ní alábàádọ́gba rẹ̀? Ó ha bọlá fún un lati pe Maria ní “ìyá Ọlọrun” ati “Obìnrin olùlàjà . . . laaarin Ẹlẹdaa ati awọn ìṣẹ̀dá Rẹ̀,” gẹgẹ bi New Catholic Encyclopedia ti sọ? Bẹẹkọ, awọn ero wọnni ńfi ìwọ̀sí lọ̀ Ọlọrun. Ko si ẹnikẹni ti o jẹ alábàádọ́gba rẹ̀; bẹẹ sì ni kò ní ìyá ẹlẹran ara kan, niwọn bi Jesu kìí tií ṣe Ọlọrun. Kò sì sí “Obìnrin olùlàjà,” kankan nitori pe Ọlọrun ti yàn kìkì “olùlàjà kan laaarin Ọlọrun ati eniyan,” Jesu.—1 Timoti 2:5, NW; 1 Johanu 2:1, 2.
Rekọja gbogbo iyemeji, oye ọpọlọpọ ni ẹkọ Mẹtalọkan ti daru ti o si ti lupọ nipa ipò tootọ ti Ọlọrun. Ó ṣèdílọ́wọ́ fun awọn eniyan lati mọ Ọba-aláṣẹ Àgbáyé naa Jehofa Ọlọrun lọna pípéye, ati kuro ninu jíjọ́sìn rẹ lori awọn ipo ti oun ti fi lelẹ. Gẹgẹ bi ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Hans Küng ti sọ ọ: “Eeṣe tí ẹnikẹni fi nilati fẹ́ lati fi ohunkohun kún èròǹgbà ti jìjẹ́ ọ̀kanṣoṣo ati jìjẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ ti Ọlọrun kiki lati lu u pọ tabi sọ jíjẹ́ ọ̀kanṣoṣo ati jíjẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ yẹn dasán?” Ṣugbọn iyẹn ni ohun ti igbagbọ ninu Mẹtalọkan ti ṣe.
Awọn wọnni tí wọn gbàgbọ́ ninu Mẹtalọkan kò “di Ọlọrun mu ninu ìmọ̀ pípéye.” (Roomu 1:28, NW) Ẹsẹ̀ yẹn sọ pẹlu pe: “Ọlọrun fi wọn sílẹ̀ sí inú ipò èrò orí tí kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà, lati maa ṣe ohun tí kò yẹ.” Ẹsẹ̀ 29 sí 31 ṣakọsilẹ diẹ lára awọn nǹkan ‘aláìyẹ’ wọnni, iru bii ‘ìṣìkàpànìyàn, rogbodiyan, jíjẹ́ elékèé sí awọn àdéhùn, aláìní ìfẹ, aláìláàánú.’ Awọn nǹkan wọnni gan-an ni awọn isin tí wọn tẹ̀wọ́gbà Mẹtalọkan fi nṣèwàhù.
Fun àpẹẹrẹ, awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹtalọkan lọpọ igba ti ṣe inunibini sí tí wọn tilẹ̀ ti pa awọn wọnni tí wọn ṣá ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ti. Wọn tilẹ̀ ti lọ àní siwaju sii. Wọn ti pa awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹtálọ́kan ẹlẹgbẹ́ wọn ní akoko ogun. Ki ni ó tún lè tubọ jẹ́ ‘aláìyẹ’ jù kí Katoliki maa pa Katoliki, Ọtọdọọsi maa pa Ọtọdọọsi, Protẹsitanti maa pa Protẹsitanti—gbogbo rẹ ni orúkọ́ Ọlọrun Mẹtalọkan kan naa?
Síbẹ̀, Jesu sọ lọna híhàn gbangba pe: “Nipa eyi ni gbogbo eniyan yoo fi mọ̀ pe, ọmọ-ẹhin mi ni ẹyin ìṣe, nigba ti ẹyin bá ní ìfẹ́ sí ọmọnikeji yin.” (Johanu 13:35) Ọ̀rọ̀ Ọlọrun mú eyi gbòòrò, ní wiwi pe: “Ninu eyi ni awọn ọmọ Ọlọrun farahan, ati awọn ọmọ Eṣu: ẹnikẹni tí kò bá ńṣe ododo kìí ṣe ti Ọlọrun, ati ẹni tí kò fẹ́ [nífẹ̀ẹ́, NW] arakunrin rẹ̀.” Ó fi awọn wọnni tí wọn npa awọn arakunrin wọn nipa tẹ̀mí wé “Keeni tí ó jẹ́ ti ẹni buburu [Satani] nì, tí ó sì pa arakunrin rẹ̀.”—1 Johanu 3:10-12.
Nipa bayii, kíkọ́ni ni awọn ẹ̀kọ́ onidarudapọ nipa Ọlọrun ti ṣamọna sí awọn ìgbésẹ̀ tí ó tẹ̀ awọn òfin rẹ̀ lójú. Niti tootọ, ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ jakejado Kristẹndọmu ni ohun tí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ara Denmark naa Søren Kierkegaard ṣapejuwe: “Kristẹndọmu ti sọ jijẹ Kristẹni nu láì kíyèsì i niti gidi.”
Ipò tẹ̀mí Kristẹndọmu bá ohun tí apọsiteli Pọọlu kọ mu pe: “Wọn jẹ́wọ́ pe wọn mọ̀ Ọlọrun; ṣugbọn nipa iṣẹ́ wọn ńsẹ́ ẹ, wọn jẹ́ ẹni ìríra, ati aláìgbọ́ràn, ati niti iṣẹ́ rere gbogbo aláìníláárí.”—Láìpẹ́, nigba ti Ọlọrun bá mú ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan buruku ti isinsinyi wá sí opin rẹ̀, Kristẹndọmu ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹ́talọ́kan ni a ó pè wá lati jíhìn. A o sì dá á lẹ́jọ́ lọna àìbáradé nitori awọn ẹ̀kọ́ ati awọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ tí ńtàbùkù sí Ọlọrun.—Matiu 24:14, 34; 25:31-34, 41, 46; Iṣipaya 17:1-6, 16; 18:1-8, 20, 24; 19:17-21.
Ṣá Mẹtalọkan Tì
KO LE si ibanidọrẹ eyikeyii lori awọn otitọ Ọlọrun. Fun ìdí yii, lati jọsin Ọlọrun lori awọn ipo ti oun fi lelẹ tumọsi ṣíṣá ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan tì. Ó tako ohun tí awọn wolii, Jesu, awọn apọsiteli, ati awọn Kristẹni ijimiji gbàgbọ́ tí wọn sì fi kọ́ni. Ó tako ohun tí Ọlọrun sọ nipa araaarẹ̀ ninu Ọ̀rọ̀ onímìísí oun funraarẹ̀. Nipa bayii, oun fúnni ni ìmọ̀ràn pe: “Mọ̀ ní àmọ̀jẹ́wọ́ pe emi nìkanṣoṣo ni Ọlọrun kò sí sí ẹlomiran kan tí ó dabii mi.”—Aisaya 46:9, TEV.
A kò le ṣiṣẹsin ifẹ Ọlọrun nipa mímú un jẹ́ onidarudapọ ati olóhun ìjìnlẹ̀. Dípò bẹẹ, bí pupọ awọn eniyan ṣe ndi ẹni ti a da lojuru nipa Ọlọrun ati awọn ète rẹ̀ sí tó, bẹẹ ni o ṣe ndunmọ Elénìní Ọlọrun, Satani Eṣu, ‘ọlọrun ayé yii’ ninu tó. Oun ni ẹni tí ó ńgbé awọn ẹ̀kọ́ èké ga lati ‘sọ ọkàn awọn tí kò gbagbọ di afọ́jú.” (2 Kọrinti 4:4) Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan pẹlu si ntẹ ifẹ ọkan awọn alufaa ṣọọṣi tí wọn fẹ́ lati pa awọn eniyan mọ labẹ ikawọ wọn lọrun, nitori pe wọn mú kí ó farahan bi ẹni pe kìkì awọn ti o kẹkọọ ìsìn nìkan ni wọn lè lóye rẹ̀.—Wo Johanu 8:44.
Ìmọ̀ pípéye nipa Ọlọrun ńmú ìtura àlááfíà ńláǹlà wá. Ó sọ wa dominira kuro lọwọ́ awọn ẹ̀kọ́ tí wọn wà ní ìforígbárí pẹlu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati kuro lọ́wọ́ awọn ètò-àjọ tí wọn ti di apẹ̀hìndà. Gẹgẹ bi Jesu ṣe sọ: “Ẹ o sì mọ otitọ, otitọ yoo sì sọ yin di ominira.”—Johanu 8:32.
Nipa bíbọlá fún Ọlọrun gẹgẹ bi Ẹni Gigajulọ tí a sì ńjọ́sìn rẹ̀ lori awọn ipo ti oun ti fi lelẹ, a lè yẹra fun ìdájọ́ tí oun yoo múwá láìpẹ́ sori Kristẹndọmu apẹ̀hìndà. Bakan naa, a lè foju lọ́nà fun ojúrere Ọlọrun nigba ti ètò-ìgbékalẹ̀ yii bá wá sí opin: “Ayé sì nkọja lọ, ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀: ṣugbọn ẹni tí ó bá ńṣe ìfẹ́ [“ìfẹ́-inú,” NW] Ọlọrun ni yoo duro láéláé.”—1 Johanu 2:17.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ère gbígbẹ́ yii ní France tí ó ti lò ọpọ ọgọrun-un ọdun ṣe ifihan ìgbadé Maria “wundia” lati ọwọ́ Mẹtalọkan. Ìgbàgbọ́ ninu Mẹtalọkan ṣamọna sí ìbọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Maria gẹgẹ bi “Ìyá Ọlọrun”