Ki Ni Bibeli Sọ Nipa Ọlọrun ati Jesu?
Ki Ni Bibeli Sọ Nipa Ọlọrun ati Jesu?
BÍ AWỌN eniyan yoo bá kà Bibeli lati paali de paali láìsí èrò àròtẹ́lẹ̀ eyikeyii nipa Mẹtalọkan, wọn yoo ha dé orí iru ironu kan bẹẹ fúnraawọn bi? Bẹẹkọ rárá.
Ohun tí yoo wá ni kedere gan-an sọkan òǹkàwé aláìṣègbè kan ni pe Ọlọrun nìkanṣoṣo ni Olodumare, Ẹlẹdaa, tí ó duro gedegbe tí ó sì yatọ si ẹnikẹni miiran, ati pe Jesu, àní ṣaaju wíwà rẹ̀ gẹgẹ bi ẹ̀dá ènìyàn pàápàá, jẹ ẹni ti o duro gedegbe ti o si yatọ, ẹni kan tí a ṣẹ̀dá, ti o jẹ ọmọ-abẹ́ Ọlọrun.
Ọ̀kan Ni Ọlọrun, Kìí Ṣe Mẹta
Ẹ̀KỌ́ Bibeli naa pe ọ̀kan ni Ọlọrun ni a ńpè ní monotheism (ẹ̀kọ̀ Ọlọrun kan ni ńbẹ). L. L. Paine, ọ̀jọ̀gbọ́n ìtàn ìdásílẹ̀ ṣọọṣi, sì fihan pe monotheism ní ọ̀nà igbekalẹ ti o mọ gaara kò yọnda fun Mẹtalọkan. “Majẹmu Laelae jẹ́ ti ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìgbàgbọ́ Ọlọrun kanṣoṣo delẹdelẹ. Ọlọrun jẹ́ ẹni kan fúnraarẹ̀. Èrò naa pe mẹtalọkan ni a ó rí níbẹ̀ . . . jẹ́ aláìní ìpilẹ̀ patapata.”
Ìyípadà eyikeyii kuro ninu ẹ̀kọ̀ ìgbàgbọ́ Ọlọrun kan ni ńbẹ ha wà lẹhin tí Jesu wá sí ilẹ̀-ayé? Paine dahun pe: “Lori kókó yii kò si iyapa laaarin Majẹmu Laelae ati Titun. Ẹ̀kọ́ ajogunba naa ti igbagbọ Ọlọrun kan ni ńbẹ nbaa niṣo. Jesu jẹ́ Juu, tí awọn òbí rẹ ti wọn jẹ Juu da a lẹkọọ ninu iwe mimọ ti Majẹmu Laelae. Títí dé ipilẹ ni ẹkọ rẹ̀ jẹ́ ti Juu; ihinrere titun kan nitootọ, ṣugbọn kìí ṣe ẹ̀kọ́ ìsìn titun. . . . Oun sì tẹwọgba ẹsẹ pataki naa ti ẹ̀kọ̀ ìgbàgbọ́ Ọlọrun kan ni ńbẹ ti awọn Juu pe: ‘Gbọ́, Isirẹli, Oluwa Ọlọrun
wa, Oluwa kan ni,’” gẹgẹ bi ero igbagbọ tirẹ̀.Awọn ọ̀rọ̀ wọnni ni a rí ní Deutaronomi 6:4. New Jerusalem Bible (NJB) ti Katoliki kà níhìn-ín pe: “Fetisilẹ, Isirẹli: Yahweh Ọlọrun wa jẹ́ ọ̀kan, Yahweh kanṣoṣo naa.” * Ninu gírámà ẹsẹ̀ naa, ọ̀rọ̀ naa “ọ̀kan” kò ní ọ̀rọ̀-ìsọdipúpọ̀ afiṣatunṣe kankan lati dámọ̀ràn pe ò tumọsi ohun miiran bikoṣe ẹni kanṣoṣo pere.
Kristẹni naa apọsiteli Pọọlu kò fi ìyípadà kankan hàn ninu ẹda Ọlọrun pẹlu, koda lẹhin tí Jesu wá sori ilẹ̀-ayé. Oun kọ̀wé pe: “Ọ̀kan ni Ọlọrun.”—Galatia 3:20; tún wo 1 Kọrinti 8:4-6.
Ní ẹgbẹẹgbẹrun ìgbà jalẹjalẹ Bibeli, Ọlọrun ni a sọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹgẹ bi ẹni kanṣoṣo. Nigba ti oun bá sọ̀rọ̀, o jẹ gẹgẹ bi ẹni kan tí a kò pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Bibeli kò tún lè ṣe kedere lori ọrọ yii jù eyi lọ. Gẹgẹ bi Ọlọrun ṣe sọ ọ: “Emi ni Jehofa, iyẹn ni orukọ mi; emi kì yoo sì fi ògo temi fúnraami fun ẹlomiran.” (Aisaya 42:8, NW) “Emi ni Yahweh Ọlọrun rẹ . . . Ẹyin ko gbọdọ ní Ọlọrun kankan yàtọ̀ sí emi.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.)—Ẹkisodu 20:2, 3, JB.
Eeṣe tí gbogbo awọn òǹkọ̀wé Bibeli tí Ọlọrun mísí yoo ṣe sọ̀rọ̀ nipa Ọlọrun gẹgẹ bi ẹni kan bí oun bá jẹ́ ẹni mẹta nitootọ? Ète wo ni iyẹn yoo ṣiṣẹ fun, bíkòṣe kí ó ṣì awọn eniyan rẹ̀ lọ́nà? Dajudaju, bí Ọlọrun bá jẹ́ awọn ẹni mẹta tí wọn parapọ̀, oun yoo ti mú kí awọn òǹkọ̀wé Bibeli rẹ̀ mu un ṣe kedere láìṣẹ́kù síbìkan kí iyemeji kankan má baà wà nipa rẹ̀. Ó kérétán awọn òǹkọ̀wé Iwe Mimọ Kristẹni lédè Giriiki tí wọn ní ìfarakanra timọtimọ pẹlu Ọmọkunrin Ọlọrun fúnraarẹ̀ yoo ti ṣe bẹẹ. Ṣugbọn wọn kò ṣe bẹẹ.
Dípò rẹ̀, ohun tí awọn òǹkọ̀wé Bibeli mú ṣe kedere láìṣẹ́kù síbìkan ni pe Ọlọrun jẹ́ Ẹni kan—Alaaye alailẹgbẹ, ti ko pin sí kélekèle tí kò si ní alábàádọ́gba kankan: “Emi ni Jehofa, kò sì sí ẹlomiran. Yàtọ̀ sí emi kò sí Ọlọrun kankan.” (Aisaya 45:5, NW) “Iwọ, orukọ ẹni kanṣoṣo tí ńjẹ́ Jehofa, iwọ ni Ọ̀gá Ogo lori ayé gbogbo.”—Saamu 83:18.
Kìí Ṣe Ọlọrun Oníye Púpọ̀
JESU pè Ọlọrun ni “Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa.” (Johanu 17:3, NW) Kò tọka láé sí Ọlọrun gẹgẹ bi ọlọrun ẹlẹni pupọ. Ìdí niyẹn tí kò fi sí ibikibi ninu Bibeli tí a ti pe ẹlomiran yatọ̀ sí Jehofa ni Olodumare. Bí kìí bá ṣe bẹẹ, ó sọ itumọ̀ ọ̀rọ̀ naa “Olodumare” dòfo. Jesu tabi ẹ̀mí mímọ́ ni a kò tilẹ pè bẹẹ, nitori pe Jehofa nìkanṣoṣo ni alaṣẹ giga julọ. Ní Jẹnẹsisi 17:1 oun polongo pe: “Emi ni Ọlọrun Olodumare.” Ẹkisodu 18:11 (NW) sì sọ pe: “Jehofa tobi ju gbogbo awọn ọlọrun yooku lọ.”
Ninu Iwe Mimọ lédè Heberu, ọ̀rọ̀ naa ʼelohʹah (ọlọrun) ní awọn oriṣi ọ̀rọ̀ ẹlẹni pupọ, tí a mọ̀ sí, ʼelo·himʹ (awọn ọlọrun) ati ʼelo·hehʹ (awọn ọlọrun ti). Awọn oriṣi ọ̀rọ̀ ẹlẹni púpọ̀ wọnyi tọkasi Jehofa ni gbogbo igba, eyi tí a ntumọ si ọ̀rọ̀ ẹlẹni kanṣoṣo naa “Ọlọrun” ní ọ̀nà yoowu kí ó jẹ́. Ǹjẹ́ awọn oriṣi ọ́rọ̀ ẹlẹni pupọ wọnyi fi Mẹtalọkan hàn bi? Bẹẹkọ, wọn kò ṣe bẹẹ. Ninu iwe naa A Dictionary of the Bible, William Smith sọ pe: “Èkukáká ni ironu alaifidimulẹ naa pé [ʼelo·himʹ] ntọkasi mẹtalọkan awọn ẹni tí wọn wà ninu Ọlọrun ẹlẹni mẹta fi rí alátìlẹ́hìn nisinsinyi laaarin awọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀. Ó jẹ́ yálà ohun tí awọn onímọ̀ gírámà pè ní ọ̀rọ̀ ìsọdipúpọ̀ ọ́láńlá tabi ó túmọ̀ sí ẹ̀kúnrẹ́rẹ agbara àtọ̀runwá, àkópọ̀ awọn agbára tí Ọlọrun nlo.”
The American Journal of Semitic Languages and Literatures sọ nipa ʼelo·himʹ pe: “O fẹrẹ jẹ igba gbogbo ni a maa ntumọ rẹ pẹlu ọrọ-iṣe ẹlẹni kanṣoṣo ninu koko gbolohun, o si maa nni ami ọrọ apọnle ẹlẹni kanṣoṣo.” Lati ṣàkàwé eyi, orúkọ-oyè naa ʼelo·himʹ farahan ni 35 ìgbà fúnraarẹ̀ ninu àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀dá, ìgbà gbogbo si ni ọ̀rọ̀-ìṣe ti nṣapejuwe ohun tí Ọlọrun sọ ati eyi tí ó ṣe jẹ́ ti ẹlẹni kanṣoṣo. (Jẹnẹsisi 1:1–2:4) Nipa bayii, ìwé naa parí èrò pe: “[ʼElo·himʹ] ni a gbọdọ ṣalaye gẹgẹ bi ọ̀rọ̀ ìsọdipúpọ̀ onítẹnumọ́, tí ó tumọ ní ìpilẹ̀ sí ìtóbi ati ọláńlá.”
ʼElo·himʹ tumọsi, kìí ṣe “awọn ẹni” bíkòṣe “awọn ọlọrun.” Nitori naa awọn wọnni tí wọn jiyàn pe ọ̀rọ̀ yii dọ́gbọ́n túmọ̀sí Mẹtalọkan sọ araawọn di awọn onigbagbọ ninu ọ̀pọ̀ Ọlọrun, awọn olùjọsìn Ọlọrun tí ó ju ẹyọkan lọ. Eeṣe? Nitori pe yoo tumọsi pe awọn ọlọrun mẹta ni ó wà ninu Mẹtalọkan. Ṣugbọn ó fẹrẹẹ jẹ́ pe gbogbo awọn alátìlẹ́hìn Mẹtalọkan ni o ṣá ojú ìwòye naa tì pe Mẹtalọkan jẹ apapọ ọlọrun mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Bibeli tun lò awọn ọ̀rọ̀ naa ʼelo·himʹ ati ʼelo·hehʹ nigba ti ó bá ntọkasi ọpọ awọn ọlọrun òrìṣà èké. (Ẹkisodu 12:12; 20:23) Ṣugbọn ni awọn ìgbà miiran ó lè tọkasi kìkì ọlọrun èké kanṣoṣo, bi ìgbà tí awọn Filisitini ntọkasi “Dagoni ọlọrun [ʼelo·hehʹ] wọn.” (Onidaajọ 16:23, 24) Baali ni a pè ní “ọlọrun kan [ʼelo·himʹ].” (1 Ọba 18:27) Ní afikun, èdè naa ni a lò fun awọn ènìyàn. (Saamu 82:1, 6) Mose ni a sọ fun pe oun yoo ṣiṣẹsin gẹgẹ bi “Ọlọrun [ʼelo·himʹ]” fun Aaroni ati fun Farao.—Ẹkisodu 4:16; 7:1.
Lọna ti o ṣe kedere, lílò awọn orúkọ-oyè ʼelo·himʹ ati ʼelo·hehʹ fun awọn ọlọrun èké, ati fun awọn ènìyàn pàápàá, kò túmọ̀sí pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ ọlọrun ẹlẹni pupọ; bẹẹ sì ni lílò ʼelo·himʹ tabi ʼelo·hehʹ fun Jehofa kò tumọsi pe oun jù ẹni kanṣoṣo lọ, pàápàá bí a bá ronu nipa awọn gbólóhùn ẹ̀rí apa yooku ninu Bibeli lori koko yii.
Jesu Ìṣẹ̀dá Ọ̀tọ̀ Kan
NIGBA ti ó wà lori ilẹ̀-ayé, Jesu jẹ́ ènìyàn, bí o tilẹ̀ jẹ́ pe ẹni pípé ni nitori pe Ọlọrun ni ó tá atare agbara iwalaaye Jesu sí inú ilé-ọlẹ̀ Maria. (Matiu 1:18-25) Ṣugbọn kìí ṣe bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ niyẹn. Oun fúnraarẹ̀ polongo pe oun “ti ọ̀run sọkalẹ wá.” (Johanu 3:13) Nitori naa ó wulẹ̀ jẹ́ iwa ẹ̀dá pe oun yoo sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ pe: “Ki ni bí ẹyin bá nilati rí Ọmọkunrin eniyan [Jesu] tí ó gòkè lọ sí ibi tí oun ti wà ṣaaju?”—Johanu 6:62, NJB.
Nipa bayii, Jesu ti walaaye ní ọ̀run ṣaaju kí ó tó wá sori ilẹ̀-ayé. Ṣugbọn ó ha jẹ́ gẹgẹ bi ọ̀kan lara awọn ẹni tí wọn wà ninu olodumare kan, mẹ́ta-nínú-ọ̀kan ayérayé ti Ọlọrun ẹlẹni mẹ́ta? Bẹẹkọ, nitori Bibeli sọ lọna ṣiṣe kedere pe ṣaaju wíwà rẹ̀ gẹgẹ bi ènìyàn, Jesu jẹ́ alaaye ẹ̀mí tí a ṣẹ̀dá, gan-an gẹgẹ bi awọn angẹli ti jẹ́ awọn alaaye ẹ̀mí ti Ọlọrun ṣẹ̀dá. Awọn angẹli tabi Jesu kò walaaye ṣaaju kí a tó ṣẹ̀dá wọn.
Jesu, ṣaaju wíwà rẹ̀ gẹgẹ bi ènìyàn, jẹ́ “akọbi gbogbo ìṣẹ̀dá.” (Kolose 1:15, NJB) Oun ni “ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá Ọlọrun.” (Iṣipaya 3:14, RS, ẹ̀dà ti Katoliki). “Ìbẹ̀rẹ̀” [Giriiki, ar·kheʹ] ni a kò lè ṣetumọ rẹ lọna ẹ̀tọ́ lati tumọsi pe Jesu ni ‘olùbẹ̀rẹ̀’ ìṣẹ̀dá Ọlọrun. Ninu awọn ìkọ́wé Bibeli rẹ, Johanu lò oniruuru ètò ọ̀rọ̀ Giriiki naa ar·kheʹ ni ohun tí ó ju 20 ìgba, awọn wọnyi nigba gbogbo maa ńní itumọ wíwọ́pọ̀ ti “ìbẹ̀rẹ̀.” Bẹẹni, Jesu ni Ọlọrun ṣẹ̀dá gẹgẹ bi ìbẹ̀rẹ̀ awọn ìṣẹ̀dá aláìṣeéfojúrí ti Ọlọrun.
Ṣakiyesi bí awọn itọkasi wọnni sí ìpilẹ̀ṣẹ̀ Jesu ṣe baramu pẹkipẹki pẹlu awọn ọ̀rọ̀ tí “Ọgbọ́n” àfiṣàpẹẹrẹ naa sọ ninu ìwé Owe ninu Bibeli pe: “Yahweh ṣẹ̀dá mi, èso àkọ́so awọn iṣẹ́-ọnà rẹ̀, ṣaaju eyiti o dagba julọ ninu awọn iṣẹ́ rẹ̀. Ṣaaju kí awọn òkè-ńlá tó fìdíkalẹ̀, ṣaaju awọn òkè kékeré, a ti bí mi; ṣaaju kí oun tó dá ilẹ̀-ayé, ìgbèríko, ati awọn ohun ìpilẹ̀ àkọ́kọ́ ninu ayé.” (Owe 8:12, 22, 25, 26, NJB) Nigba ti ó jẹ́ pe èdè-ìsọ̀rọ̀ naa “Ọgbọ́n” ni a lò lati fi duro fun ẹni naa tí Ọlọrun ṣẹ̀dá, ọpọ awọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ fohùnṣọ̀kan pe niti tootọ ó jẹ́ ọ̀rọ̀ àfiṣàpẹẹrẹ fun Jesu gẹgẹ bi ẹ̀dá ẹ̀mí kan ṣaaju wíwà rẹ̀ gẹgẹ bi ènìyàn.
Gẹgẹ bi “Ọgbọ́n” ṣaaju wíwà rẹ̀ gẹgẹ bi ẹ̀dá ènìyàn, Jesu nbaa lọ lati sọ pe oun wà “lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ [Ọlọrun] gẹgẹ bi ọ̀gá oníṣẹ́.” (Owe 8:30, JB) Ní ìbámu pẹlu ẹru iṣẹ yii gẹgẹ bi ọ̀gá oníṣẹ́, Kolose 1:16 sọ nipa Jesu pe “nipasẹ rẹ̀ Ọlọrun ṣẹ̀dá ohun gbogbo ninu ọ̀run ati lori ilẹ̀-ayé.”—Today’s English Version (TEV).
Nitori naa ó jẹ́ nipasẹ ọ̀gá òṣìṣẹ́ yii, alájọṣe rẹ̀ kékeré, kí a sọ lọna bẹẹ, ní Ọlọrun Olodumare fi ṣẹ̀dá gbogbo awọn nǹkan yooku. Bibeli ṣe àkópọ̀ ọ̀ràn naa ní ọ̀nà yii: “Fún awa Ọlọrun kan ni ńbẹ, Baba, lati ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo nǹkan ti wá . . . ati Oluwa kan, Jesu Kristi, nipasẹ ẹni tí ohun gbogbo ti wá.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ tiwa.)—1 Kọrinti 8:6, RS, Ẹ̀dà ti Katoliki.
Kò sí iyemeji kankan pe sí ọ̀gá óníṣẹ́ yii ni Ọlọrun sọ pe: “Jẹ́ kí a dá eniyan ní àwòrán wa.” (Jẹnẹsisi 1:26) Awọn kan kede pe “a” ati “wa” ninu ọ̀rọ̀ yii tọkasi Mẹtalọkan. Ṣugbọn bí iwọ bá sọ pe, ‘Jẹ́ kí a ṣe ohun kan fun araawa,’ bi o ti saba maa nri, kò sí ẹni kankan tí yoo lóye eyi pe ó túmọ̀ si pe awọn ẹni melookan papọ̀ di ẹyọkan ninu rẹ. Iwọ wulẹ̀ ní in lọkàn pe awọn ẹni meji tabi ju bẹẹ lọ yoo ṣiṣẹ́ papọ̀ lori ohun kan. Nitori naa, nigba ti Ọlọrun lò “a” ati “wa,” oun wulẹ̀ nbá ẹlomiran sọ̀rọ̀ pọ̀, ẹ̀dá ẹ̀mí rẹ̀ àkọ́kọ́, ọ̀gá oníṣẹ́, Jesu kí ó tó di ẹ̀dá ènìyàn.
A Ha Lè Dán Ọlọrun Wò Bí?
NÍ MATIU 4:1, Jesu ni a sọ pe a “dánwò lọwọ Eṣu.” Lẹhin fífí “gbogbo ilẹ̀-ọba ayé ati gbogbo ògo wọn hàn Jesu,” Satani sọ pe: “Gbogbo nǹkan wọnyi ni emi yoo fi fun ọ, bí iwọ bá wólẹ̀, tí ó foríbalẹ̀ fun mi.” (Matiu 4:8, 9) Satani ńgbìyànjú lati mú kí Jesu di aláìṣòótọ́ si Ọlọrun.
Ṣugbọn iru ìdánwò ìṣòtítọ́ wo ni iyẹn yoo jẹ́ bí Jesu bá jẹ́ Ọlọrun? Ọlọrun ha lè ṣọ̀tẹ̀ lodisi araarẹ̀ bi? Bẹẹkọ, ṣugbọn awọn angẹli ati awọn ènìyàn lè ṣọ̀tẹ̀ lodisi Ọlọrun wọn sì ṣe bẹẹ. Dídán
Jesu wo yoo lọ́gbọ́n-nínú bí oun bá jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀ kan, kìí ṣe Ọlọrun, tí ó ní ominira ìfẹ́ inú ti araarẹ̀, ẹni kan tí ó ti lè jẹ́ aláìṣòótọ́ bi ó bá yàn lati jẹ́ bẹẹ, iru bii angẹli kan tabi ènìyàn kan.Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, kò ṣeé finu moye pe Ọlọrun lè dẹ́ṣẹ̀ kí ó sì jẹ́ aláìṣòótọ́ si araarẹ̀. “Pípé ni iṣẹ́ rẹ̀ . . . Ọlọrun otitọ, . . . òdodo ati otitọ ni oun.” (Deutaronomi 32:4) Nitori naa bí Jesu bá ti jẹ́ Ọlọrun, a kì ba ti dán an wò.—Jakọbu 1:13.
Nitori pe kìí ṣe Ọlọrun, Jesu ti le di aláìṣòtítọ́. Ṣugbọn oun dúró ní olùṣòtítọ́, ó sì sọ pe: “Padà kuro lẹ́hìn mi, Satani: nitori a ti kọ̀wé rẹ̀ pe, Oluwa [Jehofa, NW] Ọlọrun rẹ ni kí iwọ kí ó foríbalẹ̀ fun, oun nìkanṣoṣo kí iwọ maa sìn.”—Matiu 4:10.
Eélòó Ni Ìràpadà Naa?
Ọ̀KAN lára awọn ìdí pataki tí Jesu fi wá sori ilẹ̀-ayé tún ní ìsopọ̀ tààràtà pẹlu Mẹtalọkan. Bibeli sọ pe: “Nitori Ọlọrun kan ni ńbẹ, onílàjà kan pẹlu laaarin Ọlọrun ati eniyan, oun pàápàá eniyan, àní Kristi Jesu; ẹni tí ó fi araarẹ̀ ṣe ìràpadà fun gbogbo eniyan.”—1 Timoti 2:5, 6.
Jesu, tí ó jẹ́ ènìyàn pípé lọna rẹgi kan, di ìràpadà tí ó jẹ́ àsanfidípò fun ohun tí Adamu pàdánù—ẹ̀tọ́ sí iwalaaye ẹ̀dá ènìyàn pípé lori ilẹ̀-ayé. Nitori naa ni apọsiteli Pọọlu ṣe lè fi ẹ̀tọ́ pè é ní “Adamu ikẹhin,” ẹni tí ó sọ ninu gbolohun kan naa pe: “Nitori bí gbogbo eniyan tí kú ninu Adamu, bẹẹni a o sì sọ gbogbo eniyan di alaaye ninu Kristi.” (1 Kọrinti 15:22, 45) Iwalaaye pípé ti Jesu ni “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí” tí ìdájọ́ òdodo àtọ̀runwá beere fun—láìpọ̀jù, láìdínkù. Kódà ìlànà ìdájọ́ òdodo ẹ̀dá ènìyàn ni pe iye owó tí a san gbọdọ ṣe wẹ́kú pẹlu àìtọ́ tí a ṣe.
Bi o ti wu ki o ri, bí Jesu, bá jẹ́ apákan Ọlọrun ẹlẹni mẹtá, iye owó ìràpadà naa ìbá ti ga fiofio ju ohun tí Ofin Ọlọrun fúnraarẹ̀ beere fun. (Ẹkisodu 21:23-25; Lefitiku 24:19-21) Ẹdá ènìyàn pípé kanṣoṣo, Adamu, ni o ṣẹ̀ ní Edeni, kìí ṣe Ọlọrun. Nitori naa ìràpàdà naa, kí ó lè wà ní ìlà pẹlu ìdájọ́ òdodo Ọlọrun nitootọ, gbọdọ jẹ́ ọgbọọgba kan tí ó pé pérépéré—ẹ̀dá ènìyàn pípé, “Adamu ikẹhin.” Nipa bayii, nigba ti Ọlọrun rán Jesu wá sori ilẹ̀-ayé gẹgẹ bi ìràpadà naa, ó mú kí Jesu jẹ́ ohun tí yoo tẹ́ ìdájọ́ òdodo lọ́rùn, kìí ṣe ẹda ẹmi ninu ẹran ara, kìí ṣe ọlọ́run ninu ara ènìyàn, bíkòṣe eniyan pípé kan, tí ó “rẹlẹ̀ diẹ ju awọn angẹli.” (Heberu 2:9; fiwe Saamu 8:5, 6) Bawo ni apá eyikeyii lára Ọlọrun ẹlẹni mẹ́ta alagbara nla kan—Baba, Ọmọkunrin, tabi ẹmí mímọ́—ṣe lè rẹlẹ̀ láé ju awọn angẹli?
Bawo Ni Oun Ṣe Jẹ́ “Ọmọkunrin Bíbí Kanṣoṣo?”
BIBELI pe Jesu ní “Ọmọkunrin bíbí kanṣoṣo” ti Ọlọrun. (Johanu 1:14; 3:16, 18; 1 Johanu 4:9) Awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹ́talọ́kan sọ pe niwọn bi Ọlọrun ti wà títíláé, bakan naa Ọmọkunrin Ọlọrun wà títíláé. Bawo ni ẹnikan ṣe lè jẹ́ ọmọkunrin ati ní akoko kan naa kí ó dàgbà tó baba rẹ̀?
Awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹ́talọ́kan kede pe ní ọ̀ràn ti Jesu, “bíbí kanṣoṣo” kìí ṣe ohun kan naa pẹlu bi ìwé àtúmọ̀ ọ̀rọ̀ ṣe tumọ “bí” tí ó tumọsi “lati bí irú-ọmọ gẹgẹ bi baba kan.” (Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary) Wọn sọ pe ní ọ̀ràn ti Jesu ó tumọsi “ìbátan aláìní ìpilẹ̀ṣẹ̀,” irú ìbátan ọmọkunrin kanṣoṣo láìní ìbí. (Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words) Iyẹn ha ba ọgbọn ironu mu loju rẹ bi? Ọkunrin kan ha lè jẹ́ baba ọmọkunrin kan láìjẹ́ pe ó bí i bi?
Siwaju sii, eeṣe tí Bibeli fi lò ọ̀rọ̀ Giriiki kan naa gan-an fun “bíbí kanṣoṣo” (gẹgẹ bi Vine ṣe gbà láìsí àlàyé eyikeyii) lati ṣapejuwe ipò ìbátan Isaaki ati Aburahamu? Heberu 11:17 sọ nipa Isaaki gẹgẹ bi “ọmọkunrin bíbí kanṣoṣo” ti Aburahamu. Kò sí iyemeji kankan pe niti ọ̀ràn Isaaki, oun ni ẹni bíbí kanṣoṣo ní ìtúmọ̀ tí ó wà déédéé, ko dọ́gba ni akoko tabi ipò pẹlu baba rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ ipilẹ Giriiki naa fun “bíbí kanṣoṣo” tí a lò fun Jesu ati Isaaki ni mo·no·ge·nesʹ, lati inu moʹnos, tí ó tumọsi “kanṣoṣo” ati giʹno·mai, gbòǹgbò ọ̀rọ̀ kan tí ó tumọsi “lati mú irú jáde” “lati di (wá di ẹda),” gẹgẹ bi Exhaustive Concordance lati ọwọ́ Strong ṣe sọ. Nipa bayii, mo·no·ge·nesʹ ni a túmọ̀ gẹgẹ bi “Kanṣoṣo tí a bí, bíbí kanṣoṣo, eyiini ni, ọmọ kanṣoṣo.”—A Greek and English Lexicon of the New Testament, lati ọwọ́ E. Robinson.
Iwe naa Theological Dictionary of the New Testament, tí Gerhard Kittel ṣe akọwe rẹ, sọ pe: “[Mo·no·ge·nesʹ] tumọsi ‘ọmọ kanṣoṣo péré,’ eyiini ni, láìsí awọn arakunrin tabi arabinrin.” Iwe yii sọ pẹlu pe ní Johanu 1:18; 3:16, 18; ati 1 Johanu 4:9, “ipò ìbátan Jesu ni a kò wulẹ̀ lè fiwé ti ọmọ kanṣoṣo pẹlu baba rẹ̀. Ó jẹ́ ipò ìbátan ẹni bíbí kanṣoṣo si Baba rẹ̀.”
Nipa bayii, iwalaaye Jesu, Ọmọkunrin bíbí kanṣoṣo naa, ní ìbẹ̀rẹ̀. Ọlọrun Olodumare ni a lè fi ẹ̀tọ́ pè ni Òbí rẹ̀, tabi Baba, ní ìtúmọ̀ kan naa tí baba ori ilẹ̀-ayé kan, gẹgẹ bi Aburahamu, gba bí ọmọkunrin kan. (Heberu 11:17) Fun ìdí yii, nigba ti Bibeli bá sọrọ nipa Ọlọrun gẹgẹ bi “Baba” Jesu, ohun tí ó sọ naa ni o tumọsi—pe wọn jẹ́ awọn ẹni meji ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ọlọrun ni àgbà. Jesu ni o kéré si i—niti akoko, ipò, agbára, ati ìmọ̀.
Nigba ti ẹni kan bá ronu rẹ̀ pe Jesu nikan kọ ni ọmọkunrin Ọlọrun nipa ti ẹ̀mí tí a ṣẹ̀dá ní ọ̀run, ó wá ṣe kedere ìdí tí èdè naa “Ọmọkunrin bíbí kanṣoṣo” fi di ohun tí a lò ní ọ̀ràn rẹ̀. Aìlóǹkà awọn alaaye ẹ̀mí tí a ṣẹ̀dá miiran, awọn angẹli, ni a tun pè ní “awọn ọmọkunrin Ọlọrun” pẹlu, ní ìtúmọ̀ kan naa gẹgẹ bi ti Adamu, nitori ipá ìwàláàyè wọn pilẹ̀ṣẹ̀ lọdọ Jehofa Ọlọrun, Ojúsun, tabi Orísun iwalaaye. (Joobu 38:7; Saamu 36:9; Luuku 3:38) Ṣugbọn gbogbo awọn wọnyi ni a ṣẹ̀dá nipasẹ “Ọmọkunrin bíbí kanṣoṣo” naa, ẹni kanṣoṣo tí Ọlọrun bí tààràtà.—Kolose 1:15-17.
A Ha Kà Jesu Sí Ọlọrun Bí?
NIGBA ti ó jẹ́ pe Jesu ni a saba maa ńpè ní Ọmọkunrin Ọlọrun ninu Bibeli, kò sí ẹnikẹni ni ọgọrun-un ọdun kìn-ínní tí ó ronu nipa rẹ̀ rí pe ó jẹ́ Ọlọrun Ọmọkunrin. Kódà awọn ẹmí èṣù, tí wọn ‘gbàgbọ́ pe Ọlọrun kan ni ńbẹ,’ mọ̀ lati inu iriri wọn ní ilẹ̀ àkóso ẹ̀mí pe Jesu kìí ṣe Ọlọrun. Nitori naa, lọna tí ó tọ́ wọn pe Jesu ni “Ọmọkunrin Ọlọrun” ti o da duro. (Jakọbu 2:19; Matiu 8:29) Nigba ti Jesu sì kú, awọn jagunjagun olórìṣà ara Roomu tí wọn duro nítòsí mọ̀ tó lati sọ pe ohun tí wọn ti gbọ́ lati ẹnu awọn ọmọlẹhin rẹ̀ gbọdọ jẹ́ otitọ pe Jesu kìí ṣe Ọlọrun, ṣugbọn pe “Ọmọkunrin Ọlọrun niyii dajudaju.”—Matiu 27:54, NW.
Fun ìdí yii, ọ̀rọ̀ kukuru naa “Ọmọkunrin Ọlọrun” tọkasi Jesu gẹgẹ bi alaaye ti o yatọ kan tí a dá, kìí ṣe gẹgẹ bi apákan Mẹtalọkan. Gẹgẹ bi Ọmọkunrin Ọlọrun, oun kò lè jẹ́ Ọlọrun fúnraarẹ̀, nitori Johanu 1:18 sọ pe: “Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọrun nigbakan rí.”—RS, ẹ̀dà Katoliki.
Awọn ọmọ-ẹhin wo Jesu gẹgẹ bi “onílàjà kan . . . laaarin Ọlọrun ati eniyan,” kìí ṣe gẹgẹ bi Ọlọrun fúnraarẹ̀. (1 Timoti 2:5) Niwọn bi ó ti jẹ́ pe bí a bá túmọ̀ rẹ̀, olùlàjà kan jẹ ẹni kan tí o yàtọ̀ sí awọn wọnni tí wọn nílò ìlàjà, yoo jẹ́ ìtakora fun Jesu lati parapọ jẹ ọkan pẹlu eyikeyii lára tọ̀túntòsì tí oun ńgbìyànjú lati là níjà. Iyẹn yoo jẹ́ dídíbọ́n lati jẹ ohun kan tí oun kò jẹ́.
Bibeli ṣe kedere ó sì baramu nipa ìbátan Ọlọrun sí Jesu. Jehofa Ọlọrun nìkanṣoṣo ni Olodumare. Oun ṣẹ̀dá Jesu ní tààràtà ṣaaju wíwà rẹ̀ gẹgẹ bi ẹ̀dá ènìyàn. Nipa bayii, Jesu ní ìbẹ̀rẹ̀ kan oun kò sì lè dọ́gba bakan naa pẹlu Ọlọrun ninu agbára tabi ayérayé láéláé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 7 Orukọ Ọlọrun ni a túmọ̀ sí “Yahweh” ninu awọn ìtúmọ̀ kan, “Jehofa” ní awọn miiran.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]
Ní ṣíṣẹ̀dá rẹ̀ lati ọwọ́ Ọlọrun, Jesu wà ní ipò keji niti akoko, agbára, ati ìmọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jesu sọ pe oun ti wàláàyè ṣaaju didi ẹ̀dá ènìyàn, niwọn bi Ọlọrun ti ṣẹ̀dá rẹ̀ gẹgẹ bi ìbẹ̀rẹ̀ awọn ìṣẹ̀dà Ọlọrun tí a ko lè fojúrí