Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjọba Kan “Tí A Kì Yóò Run Láé”

Ìjọba Kan “Tí A Kì Yóò Run Láé”

Orí Kẹwàá

Ìjọba Kan “Tí A Kì Yóò Run Láé”

1. Kókó wo ni àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé jálẹ̀ gbogbo ìtàn ìran èèyàn ti mú ṣe kedere?

ÀWỌN ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ń jẹ́rìí sí òtítọ́ náà pé kíkọ̀ táwọn èèyàn kọ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ sílẹ̀ tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti ṣàkóso ara wọn kò tíì mú ayọ̀ wá. Kò tíì sí ètò ìjọba èèyàn kankan tó mú àwọn àǹfààní tí kò ní ojúsàájú nínú wá fún aráyé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ti gòkè àgbà nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì dé ìwọ̀n tí a ò rírú ẹ̀ rí, kò tíì ṣeé ṣe fún wọn láti mú àìsàn kúrò bẹ́ẹ̀ ni wọn ò tíì rí oògùn ikú ṣe, kódà fún ẹnì kan ṣoṣo pàápàá. Ìṣàkóso èèyàn kò tíì mú ogun, ìwà ipá, ìwà ọ̀daràn, ìwà ìbàjẹ́ àti ipò òṣì kúrò. Àwọn ìjọba aninilára ṣì ń tẹ àwọn èèyàn lórí ba ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. (Oníwàásù 8:9) Ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, ojúkòkòrò àti àìmọ̀kan ṣì jẹ́ àwọn kókó tó ń fa bíba ilẹ̀, omi àti afẹ́fẹ́ jẹ́. Ìná àpà táwọn aláṣẹ ń náwó ń mú kó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti ní àwọn ohun kòṣeémáàní ìgbésí ayé. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tí èèyàn ti fi ń ṣàkóso ti mú kókó náà ṣe kedere pé: “Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.

2. Kí ni ojútùú kan ṣoṣo tó wà fún ìṣòro aráyé?

2 Kí ni ojútùú rẹ̀? Ìjọba Ọlọ́run ni, èyí tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà fún pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Nínú 2 Pétérù 3:13, a pe Ìjọba Ọlọ́run ní “ọ̀run tuntun,” èyí tí yóò ṣàkóso lórí “ayé tuntun,” ìyẹn àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tó jẹ́ olódodo. Ìjọba Ọlọ́run yìí ṣe pàtàkì débi pé, orí ẹ̀ ni Jésù gbé gbogbo ìwàásù rẹ̀ kà. (Mátíù 4:17) Ó jẹ́ ká mọ bó ṣe gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì tó nínú ìgbésí ayé wa nígbà tó rọ̀ wá pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.”—Mátíù 6:33.

3. Kí nìdí tí mímọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fi jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú gan-an báyìí?

3 Mímọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ti di ohun kánjúkánjú báyìí. Ìdí ni pé Ìjọba yẹn yóò gbégbèésẹ̀ láìpẹ́ láti yí ìṣàkóso ayé yìí padà títí láé fáàbàdà. Dáníẹ́lì 2:44 sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [àwọn ìjọba tó ń ṣàkóso lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí], Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ [ní ọ̀run] èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn [àwọn èèyàn kò tún ní í ṣàkóso lórí ayé mọ́ láé]. Yóò fọ́ ìjọba [ti lọ́wọ́lọ́wọ́] wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Ìjọba náà yóò tipa báyìí mú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí wá sópin nípa pípa gbogbo ètò àwọn nǹkan búburú yìí run pátápátá. Nígbà náà, ìṣàkóso ayé nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run kò ní mú àríyànjiyàn kankan lọ́wọ́. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká kún fún ọpẹ́ gan-an pé ìtura tí èyí máa mú wá ti sún mọ́lé báyìí!

4. Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ìjọba náà, kí ló ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run lọ́dún 1914, kí ló sì mú kí èyí ṣe pàtàkì sí wa?

4 Ní ọdún 1914, Ọlọ́run sọ Kristi Jésù di Ọba ó sì fún un láṣẹ láti “máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá [rẹ̀].” (Sáàmù 110:1, 2) Lọ́dún yẹn kan náà ni “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ti ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí bẹ̀rẹ̀. (2 Tímótì 3:1-5, 13) Àkókò kan náà làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Dáníẹ́lì rí nínú ìran alásọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run ní ti gidi. Jèhófà Ọlọ́run, “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé” náà fún Ọmọ Ènìyàn, tí í ṣe Jésù Kristi, ní “agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun.” Nígbà tí Dáníẹ́lì ń sọ̀rọ̀ nípa ìran náà, ó kọ̀wé pé: “Agbára ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ agbára ìṣàkóso tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin tí kì yóò kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ sì jẹ́ èyí tí a kì yóò run.” (Dán. 7:13, 14) Ìjọba ọ̀run tó wà níkàáwọ́ Kristi Jésù yìí ni Ọlọ́run máa lò láti mú kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo gbádùn àìlóǹkà ohun dídára, èyí tó pinnu rẹ̀ nígbà tó fi àwọn òbí wa àkọ́kọ́ sínú Párádísè.

5. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wo nípa Ìjọba náà ló jẹ wá lọ́kàn gan-an, kí ló sì fà á?

5 Ṣé ó wù ọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba yẹn? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá fẹ́ láti mọ bí a ṣe ṣètò ìjọba ọ̀run yìí àti ọ̀nà tó ń gbà ṣiṣẹ́. Wàá fẹ́ láti mọ ohun tó ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́, ohun tí yóò ṣe lọ́jọ́ iwájú àti ohun tó ń béèrè pé kí o ṣe. Bó o ti ń ṣàyẹ̀wò Ìjọba náà kínníkínní, ńṣe ló yẹ kí ìmọrírì tó o ní fún un máa pọ̀ sí i. Tó o bá fọwọ́ pàtàkì mú ìṣàkóso Ìjọba yìí, ara rẹ á máa wà lọ́nà láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa àwọn nǹkan àgbàyanu tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún àwọn ẹ̀dá èèyàn onígbọràn.—Sáàmù 48:12, 13.

Àwọn Tó Máa Jẹ́ Alákòóso Nínú Ìjọba Ọlọ́run

6. (a) Ipò ọba aláṣẹ ta ni Ìwé Mímọ́ fi hàn pé Ìjọba Mèsáyà ń ṣojú fún? (b) Kí ló yẹ kí àwọn ohun tí à ń kọ́ nípa Ìjọba náà sún wa ṣe?

6 Ọ̀kan lára àwọn nǹkan àkọ́kọ́ tí irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ kó o mọ̀ ni pé, Ìjọba Mèsáyà jẹ́ àfihàn ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ fúnra rẹ̀. Jèhófà ló fún Ọmọ rẹ̀ ní “agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba.” Lẹ́yìn tí a gbé agbára wọ Ọmọ Ọlọ́run láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso bí Ọba, àwọn ohùn kan láti ọ̀run polongo lọ́nà tó ṣe wẹ́kú pé: “Ìjọba ayé di ìjọba Olúwa wa [Jèhófà Ọlọ́run] àti ti Kristi rẹ̀, [Jèhófà] yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé àti láéláé.” (Ìṣípayá 11:15) Nítorí náà, gbogbo àkíyèsí tá a bá ṣe nípa Ìjọba yìí àti ohun tó ń gbé ṣe lè túbọ̀ mú wa sún mọ́ Jèhófà fúnra rẹ̀ sí i. Àwọn ohun tí à ń kọ́ gbọ́dọ̀ mú ká fẹ́ láti bọ̀wọ̀ fún ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ títí ayé.

7. Kí nìdí tínú wa fi dùn gan-an pé Jésù Kristi ni Alákòóso tó jẹ́ Igbákejì Jèhófà?

7 Tún gbé kókó náà pé Jèhófà ti gbé Jésù Kristi ka orí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Alákòóso tó jẹ́ Igbákejì rẹ̀ yẹ̀ wò. Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti lo Jésù bí Ọ̀gá Òṣìṣẹ́ láti dá ayé àti ènìyàn, ó mọ àwọn ohun tó ń jẹ wá níyà ju bí ẹnikẹ́ni nínú wa ti mọ̀ ọ́n lọ. Yàtọ̀ síyẹn, látìgbà ìwáṣẹ̀ aráyé ló ti ní ‘ìfẹ́ni sí àwọn ọmọ ènìyàn.’ (Òwe 8:30, 31; Kólósè 1:15-17) Ìfẹ́ tó ní sí àwa èèyàn pọ̀ débi pé, ó dìídì wá sórí ilẹ̀ ayé ó sì fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ láti fi ṣe ìràpadà fún wa. (Jòhánù 3:16) Nípa bẹ́ẹ̀, ó pèsè ọ̀nà àbáyọ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú fún wa, ó sì fún wa láǹfààní àtiwàláàyè títí ayérayé.—Mátíù 20:28.

8. (a) Láìdà bí ìjọba èèyàn, ìdí wo ni ìjọba Ọlọ́run fi máa wà títí ayé? (b) Àjọṣe wo ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà ní pẹ̀lú ìjọba ọ̀run?

8 Ìṣàkóso tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó sì máa wà títí lọ gbére ni Ìjọba Ọlọ́run. Jíjẹ́ tó jẹ́ Ìjọba tó máa wà títí ayé la fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípasẹ̀ òtítọ́ náà pé Jèhófà kì í kú. (Hábákúkù 1:12) Jésù Kristi, ẹni tí Ọlọ́run fa ìṣàkóso náà lé lọ́wọ́ kò dà bí àwọn ọba èèyàn, òun náà kò lè kú. (Róòmù 6:9; 1 Tímótì 6:15, 16) Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì èèyàn yóò wà pẹ̀lú Kristi lórí àwọn ìtẹ́ ní ọ̀run. Wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti inú “gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè.” Ọlọ́run ti fún àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ní ìyè àìleèkú. (Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1-4; 1 Kọ́ríńtì 15:42-44, 53) Èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn ti wà lọ́run báyìí, àwọn tó sì ṣẹ́ kù lára wọn tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé la mọ̀ sí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” lónìí, tí wọ́n ń fi ìdúró ṣinṣin mú ire Ìjọba náà tẹ̀ síwájú lórí ilẹ̀ ayé níbí.—Mátíù 24:45-47.

9, 10. (a) Àwọn ohun tó ń fa ìpínyà àti ìbàjẹ́ wo ni Ìjọba náà máa mú kúrò? (b) Bá ò bá fẹ́ di ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run, àwọn nǹkan wo ni kò yẹ́ ká lọ́wọ́ nínú rẹ̀?

9 Láìpẹ́ sí ìsinsìnyí, tí àkókò tí Jèhófà yàn bá tó, yóò rán àwọn agbo ọmọ ogun amúdàájọ́ṣẹ rẹ̀ pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ fífọ ilẹ̀ ayé mọ́ tónítóní. Wọ́n á pa gbogbo àwọn èèyàn tó ti pinnu lọ́kàn wọn pé àwọn ò ní í fi ti ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ṣe run pátápátá, ìyẹn àwọn tó fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn ìpèsè onífẹ̀ẹ́ tó ṣe nípasẹ̀ Jésù Kristi. (2 Tẹsalóníkà 1:6-9) Ọjọ́ Jèhófà ni ọjọ́ yẹn máa jẹ́, ìyẹn àkókò tó ti ń dúró dè láti dá jíjẹ́ tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run láre. ‘Wò ó! Àní ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀, ó níkà pẹ̀lú ìbínú kíkan àti pẹ̀lú ìbínú jíjófòfò, . . . kí ó lè pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ilẹ̀ náà rẹ́ ráúráú kúrò lórí rẹ̀.’ (Aísáyà 13:9) “Ọjọ́ yẹn jẹ́ ọjọ́ ìbínú kíkan, ọjọ́ wàhálà àti làásìgbò, ọjọ́ ìjì àti ìsọdahoro, ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù, ọjọ́ àwọsánmà àti ìṣúdùdù tí ó nípọn.”—Sefanáyà 1:15.

10 Gbogbo ìsìn èké àti gbogbo ìjọba èèyàn pátá, títí kan àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, tí alákòóso búburú ayé yìí tí a kò lè fojú rí ń darí la máa pa run yán-ányán-án. Gbogbo àwọn tó fi ara wọn hàn pé ti ayé yìí làwọn jẹ́ nípa gbígbé ìgbé ayé ànìkànjọpọ́n, ti àìṣòótọ́ àti ti ìṣekúṣe ló máa ṣègbé. Ọlọ́run á fi Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ pa mọ́ fún ẹgbẹ̀rún ọdún wọn ò sì ní í ní àjọṣe kankan pẹ̀lú àwọn olùgbé ayé mọ́. Nígbà yẹn, Ìjọba Ọlọ́run ni yóò máa ṣàkóso gbogbo ọ̀ràn ayé pátá láìkù síbì kan. Ìtura tí kò ṣeé fẹnu sọ nìyẹn á mà jẹ́ o fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo!—Ìṣípayá 18:21, 24; 19:11-16, 19-21; 20:1, 2.

Àwọn Ète Ìjọba Náà àti Bí Yóò Ṣe Nímùúṣẹ

11. (a) Ọ̀nà wo ni Ìjọba Mèsáyà yóò gbà mú ète Jèhófà fún ilẹ̀ ayé ṣẹ? (b) Kí ni ìṣàkóso Ìjọba náà yóò túmọ̀ sí fún àwọn èèyàn tí yóò máa gbé lórí ilẹ̀ ayé nígbà yẹn?

11 Ìjọba Mèsáyà yóò mú àwọn ìpinnu tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé yìí níbẹ̀rẹ̀ ṣẹ ní kíkún. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:8, 9, 15) Títí di bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, aráyé kọ̀, wọn ò fara mọ́ ète yẹn. Àmọ́ o, àwọn olùgbé ‘ilẹ̀ ayé tí ń bọ̀’ yóò jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Jésù Kristi. Gbogbo àwọn tó bá la ìdájọ́ Jèhófà lórí ètò àwọn nǹkan ògbólógbòó yìí já yóò ṣíṣẹ́ níṣọ̀kan lábẹ́ Ọba náà, Kristi. Tìdùnnú-tìdùnnú ni wọ́n á máa fi ṣe ohunkóhun tó bá pa láṣẹ pé kí wọ́n ṣe, kí gbogbo ayé lè di Párádísè. (Hébérù 2:5-9) Gbogbo èèyàn ni yóò gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn wọ́n yóò sì jàǹfààní ní kíkún látinú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun tí ilẹ̀ ayé yóò máa mú jáde.—Sáàmù 72:1, 7, 8, 16-19; Aísáyà 65:21, 22.

12. Ọ̀nà wo ni ìjẹ́pípé ara àti ti èrò inú á fi dé bá àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba náà?

12 Nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, ẹni pípé ni wọ́n, ète Ọlọ́run sì ni pé kí wọ́n fi ọmọ kún ilẹ̀ ayé, kí gbogbo wọn sì máa gbádùn èrò inú àti ara tí ó pé. Ọlọ́run á mú ète yẹn ṣẹ lọ́nà híhẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba náà. Èyí ń béèrè fún mímú gbogbo ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ ti dá sílẹ̀ kúrò, ìdí èyí sì ni Kristi tún fi jẹ́ Àlùfáà Àgbà tí kì í ṣe Ọba nìkan. Yóò fi sùúrù ran àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ onígbọràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní látinú ìtóye ẹbọ tí ń ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀, èyí tó fi ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn rẹ̀ ṣe.

13. Àwọn àǹfààní ti ara wo la máa gbádùn lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run?

13 Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba, àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé á gbádùn ìlera ara tí kò tíì sírú ẹ̀ rí. “Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.” (Aísáyà 35:5, 6) Ara tí ọjọ́ ogbó tàbí àìsàn ti sọ dìdàkudà yóò padà jọ̀lọ̀ ju ti ọmọ kékeré lọ, àwọn àrùn bárakú tí ń sọ ara di hẹ́gẹhẹ̀gẹ kò ní sí mọ́, ìlera tó jíire ló máa rọ́pò wọn. “Kí ara rẹ̀ jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe; kí ó padà sí àwọn ọjọ́ okun inú ti ìgbà èwe rẹ̀.” (Jóòbù 33:25) Ọjọ́ náà dé tán, nígbà tí kò ní sí ìdí fún ẹnikẹ́ni mọ́ láti sọ pé, “Àìsàn ń ṣe mí.” Nítorí kí ni? Nítorí pé Ọlọ́run máa dá àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìnira ẹ̀ṣẹ̀ àtàwọn àbájáde rẹ̀ bíburú jáì. (Aísáyà 33:24; Lúùkù 13:11-13) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run “yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.

14. Kí ni dídé ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn wé mọ́?

14 Àmọ́, dídé ìjẹ́pípé kọjá wíwulẹ̀ ní ara àti èrò inú tó dá ṣáṣá. Ó tún kan gbígbé àwọn ànímọ́ Jèhófà yọ dáadáa, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ní ‘àwòrán Ọlọ́run’ ni a dá wa, ‘ní ìrí rẹ̀.’ (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Kí ìyẹn tó lè ṣeé ṣe, a máa nílò ẹ̀kọ́ tó pọ̀ gan-an. ‘Òdodo ni yóò máa gbé’ nínú ayé tuntun. Èyí ló mú Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé, “òdodo ni àwọn olùgbé ilẹ̀ eléso yóò kọ́ dájúdájú.” (2 Pétérù 3:13; Aísáyà 26:9) Ànímọ́ òdodo yìí ń yọrí sí àlàáfíà—láàárín àwọn èèyàn látinú gbogbo ẹ̀yà, láàárín àwọn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ tímọ́tímọ́, nínú ìdílé ẹni, àti ní pàtàkì jù lọ, pẹ̀lú Ọlọ́run fúnra rẹ̀. (Sáàmù 85:10-13; Aísáyà 32:17) Àwọn tó bá kọ́ òdodo yóò bẹ̀rẹ̀ sí í lóye ohun tí ìfẹ́ inú Ọlọ́run fún wọn jẹ́. Bí ìfẹ́ fún Jèhófà ti ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa lọ́kàn wọn, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé àwọn ọ̀nà rẹ̀ nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wọn. Wọ́n á lè sọ gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ pé, ‘nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wu Bàbá mi.’ (Jòhánù 8:29) Ìgbésí ayé á mà dùn nígbà ti gbogbo èèyàn bá dí ẹni tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ o!

Àwọn Àṣeyọrí Tó Ti Hàn Kedere Báyìí

15. Nípa lílo àwọn ìbéèrè tó wà nínú ìpínrọ̀ yìí, sọ àwọn àṣeyọrí tí Ìjọba náà ti ṣe àtàwọn ohun tó yẹ ká máa ṣe báyìí.

15 A ti ń rí àwọn àṣeyọrí jíjọnilójú tí Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ ń ṣe. Àwọn ìbéèrè àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí yóò rán ọ létí díẹ̀ lára àwọn àṣeyọrí yìí, títí kan àwọn ohun tí gbogbo àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba náà lè ṣe tó sì yẹ kí wọ́n máa ṣe nísinsìnyí.

Ta ni Ìjọba náà kọ́kọ́ dojú ìjà kọ, kí ló sì jẹ́ àbájáde rẹ̀? (Ìṣípayá 12:7-10, 12)

Kíkó àwọn mẹ́ńbà tó kù nínú ẹgbẹ́ wo jọ ni Kristi gbájú mọ́ látìgbà tó ti di Ọba? (Ìṣípayá 14:1-3)

Iṣẹ́ wo ni Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé òun máa ṣe lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ́ sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Mátíù 25:31-33 ṣe fi hàn?

Iṣẹ́ àkọ́múṣe wo là ń ṣe lóde òní? Àwọn wo ló ń kópa nínú rẹ̀? (Sáàmù 110:3; Mátíù 24:14; Ìṣípayá 14:6, 7)

Kí nìdí táwọn olóṣèlú àtàwọn ẹlẹ́sìn tó ń ṣàtakò ò fi lè fòpin sí iṣẹ́ ìwàásù náà? (Sekaráyà 4:6; Ìṣe 5:38, 39)

Ìyípadà wo ló ti wáyé nínú ìgbésí ayé àwọn tó fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run? (Aísáyà 2:4; 1 Kọ́ríńtì 6:9-11)

Ìjọba Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún

16. (a) Báwo ni ìṣàkóso Kristi ṣe máa gùn tó? (b) Àwọn nǹkan àgbàyanu wo ló máa ṣẹlẹ̀ láàárín àkókò náà àti lẹ́yìn náà?

16 Lẹ́yìn tí á bá ti ju Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, Jésù Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jẹ́ ajùmọ̀jogún pẹ̀lú rẹ̀ yóò ṣàkóso bí ọba àti àlùfáà fún ẹgbẹ̀rún ọdún. (Ìṣípayá 20:6) Láàárín àkókò yẹn, wọ́n á sọ aráyé di pípé, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí Ádámù dá sílẹ̀ yóò sì di ohun tí a mú kúrò títí ayé. Ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà, lẹ́yìn tí Jésù bá ti ṣe iṣẹ́ tá a yàn fún un gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà tó jẹ́ Ọba àti Àlùfáà láṣeyọrí, yóò wá ‘fa ìjọba náà lé’ Bàbá rẹ̀ lọ́wọ́, “kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.” (1 Kọ́ríńtì 15:24-28) Ìgbà yẹn gan-an la óò wá tú Sátánì sílẹ̀ fúngbà díẹ̀ láti dán aráyé tí a ti rà padà wò, láti mọ̀ bóyá wọ́n fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Lẹ́yìn tí ìdánwò ikẹyìn yẹn bá ti parí, Jèhófà yóò pa Sátánì àtàwọn ọlọ̀tẹ̀ tó fara mọ́ ọn run. (Ìṣípayá 20:7-10) Àwọn tó bá fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, tí wọ́n gbà pé òun ló ní ẹ̀tọ́ láti ṣàkóso á ti fi ìdúróṣinṣin wọn hàn ní kíkún nígbà yẹn. Wọ́n á wá di ẹni tó ní àjọṣe tó dára gan-an pẹ̀lú Jèhófà, yóò sì tẹ́wọ́ gbà wọ́n bí àwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ tó fọwọ́ sí pé wọ́n yẹ fún ìyè ayérayé.—Róòmù 8:21.

17. (a) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Ìjọba náà ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún? (b) Ọ̀nà wo ló fi jẹ́ òótọ́ pé Ìjọba náà ni a “kì yóò run láé”?

17 Nípa bẹ́ẹ̀, ipa tí Jésù fúnra rẹ̀ àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ń kó nínú ọ̀ràn ilẹ̀ ayé yóò wá sópin. Iṣẹ́ wo ni wọ́n á wá máa ṣe lọ́jọ́ iwájú? Bíbélì ò sọ ọ́. Àmọ́ tá a bá fi tòótọ́tòótọ́ rọ̀ mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, a ó wà láàyè ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà láti mọ ète tí Jèhófà ní fún wọn àti fún àgbàyanu àgbáálá ayé rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ìṣàkóso Kristi ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún yóò jẹ́ èyí “tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin” Ìjọba rẹ̀ yóò sì jẹ́ èyí “tí a kì yóò run.” (Dáníẹ́lì 7:14) Lọ́nà wo? Ìdí kan ni pé, ẹ̀tọ́ láti ṣàkóso kò tún ní í bọ́ sọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ní ète mìíràn lọ́kàn mọ́, nítorí pé Jèhófà ní yóò jẹ́ Alákòóso. Bákan náà, Ìjọba náà ni “a kì yóò run láé” nítorí pé àwọn ohun tó ti gbé ṣe yóò wà títí láé. (Dáníẹ́lì 2:44) Mèsáyà tó jẹ́ Ọba òun Àlùfáà náà, àtàwọn tó jẹ́ ọba àti àlùfáà pẹ̀lú rẹ̀ la ó sì máa bọlá fún títí ayé nítorí fífi tí wọ́n fi òtítọ́ sin Jèhófà.

Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò

• Kí nìdí tí Ìjọba Ọlọ́run fi jẹ́ ojútùú kan ṣoṣo tó wà fún ìṣòro aráyé? Ìgbà wo ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso?

• Kí ló fà ọ́ mọ́ra jù nípa Ìjọba Ọlọ́run àtohun tó máa gbé ṣe?

• Àwọn àṣeyọrí wo ni Ìjọba náà ti ṣe tá a lè rí báyìí, ipa wo la sì ń kó nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwés 92, 93]

Òdodo ni gbogbo èèyàn yóò kọ́ lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run