Ìtumọ̀ Ìrìbọmi Tó O Ṣe
Orí Kejìlá
Ìtumọ̀ Ìrìbọmi Tó O Ṣe
1. Èé ṣe tí ṣíṣe ìrìbọmi fi gbọ́dọ̀ jẹ gbogbo wa lọ́kàn?
LỌ́DÚN 29, Sànmánì Tiwa, Jòhánù Oníbatisí ri Jésù bọmi nínú Odò Jọ́dánì. Jèhófà fúnra rẹ̀ ń wò ó, ó sì fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gbà á. (Mátíù 3:16, 17) Jésù tipa báyìí fi àpẹẹrẹ tí gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yóò máa tẹ̀ lé lélẹ̀. Ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn ni Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni yìí pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.” (Mát. 28:18, 19) Ṣé a ti batisí ìwọ náà níbàámu pẹ̀lú àṣẹ tí Jésù pa yẹn? Bí o kò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀, ṣé ò ń múra láti ṣe bẹ́ẹ̀?
2. Àwọn ìbéèrè wo tó ní í ṣe pẹ̀lú batisí ló ń fẹ́ ìdáhùn?
2 Bóyá o ti ṣe batisí tàbí o ṣẹ̀ṣẹ̀ ń múra láti ṣe bẹ́ẹ̀, níní òye tó ṣe kedere nípa ohun tí batisí jẹ́ ṣe pàtàkì fún gbogbo èèyàn tó bá fẹ́ sin Jèhófà tó sì fẹ́ gbé nínú ayé tuntun òdodo rẹ̀. Lára àwọn ìbéèrè tó yẹ ká wá ìdáhùn sí nìwọ̀nyí: Ṣé ohun kan náà ni ìrìbọmi táwọn Kristẹni ń ṣe lónìí àti èyí tí Jésù ṣe túmọ̀ sí? Kí ló túmọ̀ sí láti batisí “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́?” Àwọn nǹkan wo ló wé mọ́ gbígbé níbàámu pẹ̀lú ohun tí ìrìbọmi Kristẹni dúró fún?
Àwọn Ìrìbọmi Tí Jòhánù Ṣe Fáwọn Èèyàn
3. Ọ̀dọ̀ àwọn wo ni a fi ìbatisí Jòhánù mọ sí?
3 Ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà ṣáájú kí Jésù tó ṣèrìbọmi, Jòhánù Mátíù 3:1, 2) Àwọn èèyàn gbọ́ ohun tí Jòhánù sọ wọ́n sì ṣègbọràn. Wọ́n jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní gbangba, wọ́n ronú pìwà dà, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Jòhánù kó lè batisí wọn nínú Odò Jọ́dánì. Àwọn Júù nìkan ni ìbatisí yẹn wà fún.—Lúùkù 1:13-16; Ìṣe 13:23, 24.
Oníbatisí lọ ń wàásù ní aginjù Jùdíà, ó ń sọ pé: “Ẹ ronú pìwà dà, nítorí ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.” (4. Èé ṣe tó fi di dandan pé kí àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní ronú pìwà dà ní kíákíá?
4 Àwọn Júù wọ̀nyẹn nílò ìrònúpìwàdà ní kíákíá. Lọ́dún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, lórí Òkè Sínáì, àwọn baba ńlá wọn dá májẹ̀mú kan tó kan gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn. Ó jẹ́ àdéhùn pàtàkì tó gbàrònú gidigidi tí wọ́n bá Jèhófà Ọlọ́run ṣe. Àmọ́ nítorí àwọn ìwàkiwà wọn tó lé kenkà, wọn ò gbé níbàámu pẹ̀lú májẹ̀mú yẹn, ni Ọlọ́run bá fi májẹ̀mú náà dá wọn lẹ́jọ́. Nígbà tó fi máa di ọjọ́ Jésù, ipò wọn ti burú jáì. “Ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà” tí Málákì sọ tẹ́lẹ̀ ti sún mọ́lé. Lọ́dún 70, Sànmánì Tiwa, “ọjọ́” yẹn dé, nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù run títí kan tẹ́ńpìlì rẹ̀ àtàwọn Júù tó lé ní mílíọ̀nù kan. Ọlọ́run rán Jòhánù Oníbatisí, ẹni tó jẹ́ onítara fún ìjọsìn tòótọ́ jáde ṣáájú ìparun yẹn, “láti pèsè sílẹ̀ fún Jèhófà àwọn ènìyàn kan tí a ti múra sílẹ̀.” Ó pọn dandan kí wọ́n ronú pìwà dà fún dídà tí wọ́n da májẹ̀mú Òfin Mósè kí wọ́n sì múra tán láti tẹ́wọ́ gba Ọmọ Ọlọ́run náà, Jésù, ẹni tí Jèhófà ń rán bọ̀ wá bá wọn.—Málákì 4:4-6; Lúùkù 1:17; Ìṣe 19:4.
5. (a) Nígbà tí Jésù wá láti ṣe ìbatisí, kí ló dé tí Jòhánù fi bẹ̀rẹ̀ sí í bi í ní ìbéèrè? (b) Àpẹẹrẹ kí ni ìrìbọmi Jésù jẹ́?
5 Jésù fúnra rẹ̀ wà lára àwọn tó tọ Jòhánù wá láti Mátíù 3:13-15) Nítorí pé Jésù kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan, ìbatisí tirẹ̀ kì í ṣe àpẹẹrẹ ìrònúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò sídìí fún un láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, níwọ̀n bó ti jẹ́ apá kan orílẹ̀-èdè kan tá a ti yà sí mímọ́ fún Jèhófà tẹ́lẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìrìbọmi tó ṣe nígbà tó pé ẹni ọgbọ̀n ọdún yàtọ̀ pátápátá, ó sì jẹ́ àpẹẹrẹ fífi ara rẹ̀ fún Baba rẹ̀ ọ̀run láti túbọ̀ ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
ṣèrìbọmi. Àmọ́ fún ìdí wo? Níwọ̀n bí Jòhánù ti mọ̀ pé Jésù kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan tó fẹ́ jẹ́wọ́ rẹ̀, ó sọ pé: “Èmi ni ó yẹ kí a batisí láti ọwọ́ rẹ, ìwọ ha sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ mi bí?” Àmọ́ ìbatisí Jésù jẹ́ àpẹẹrẹ ohun kan tó yàtọ̀. Èyí ló mú kí Jésù dáhùn pé: “Jọ̀wọ́ rẹ̀, lọ́tẹ̀ yìí, nítorí ní ọ̀nà yẹn ni ó yẹ fún wa láti mú gbogbo èyí tí ó jẹ́ òdodo ṣẹ.” (6. Báwo ni ṣíṣe ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ṣe pàtàkì gan-an tó lójú Jésù?
6 Ìfẹ́ Ọlọ́run fún Jésù Kristi kan ṣíṣe àwọn ìgbòkègbodò tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba náà. (Lúùkù 8:1) Ó tún kan fífi ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé rẹ̀ rúbọ láti fi ṣe ìràpadà kó sì tún jẹ́ ìpìlẹ̀ fún májẹ̀mú tuntun. (Mátíù 20:28; 26:26-28; Hébérù 10:5-10) Jésù kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ohun tí ìrìbọmi rẹ̀ dúró fún. Kò jẹ́ kí ohun mìíràn gba òun lọ́kàn. Títí dé òpin ìwàláàyè rẹ̀ ló fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sì fi wíwàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run ṣe olórí iṣẹ́ rẹ̀.—Jòhánù 4:34.
Ìrìbọmi Tí Àwọn Kristẹni Ọmọ Ẹ̀yìn Ṣe
7. Láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33, Sànmánì Tiwa, kí ni a sọ fún àwọn Kristẹni láti ṣe nípa ìbatisí?
7 Àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti ṣèrìbọmi tẹ́lẹ̀ lọ́dọ̀ Jòhánù, ẹ̀yìn náà ló wá darí wọn sí Jésù láti di ara àwọn tó máa wà nínú Ìjọba ọ̀run. (Jòhánù 3:25-30) Lábẹ́ ìdarí Jésù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí náà batisí àwọn èèyàn kan, ìbatisí yìí sì ṣe pàtàkì bí èyí tí Jòhánù ṣe fáwọn èèyàn. (Jòhánù 4:1, 2) Àmọ́, láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33, Sànmánì Tiwa ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí i mú àṣẹ tá a fún wọn láti “batisí . . . ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́” ṣẹ. (Mátíù 28:19) Wàá jàǹfààní gan-an tó o bá lè ṣàtúnyẹ̀wò ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí.
8. Kí ló túmọ̀ sí láti di ẹni tá a batisí “ní orúkọ Baba”?
8 Kí ló túmọ̀ sí láti di ẹni tí a batisí “ní orúkọ Baba”? Ó túmọ̀ sí títẹ́wọ́ gba orúkọ, ipò, ọlá àṣẹ, ète, àti àwọn òfin Baba. Gbé àwọn nǹkan tó wé mọ́ èyí yẹ̀ wò. (1) Ní ti orúkọ rẹ̀, Sáàmù 83:18 sọ pé: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (2) Ní ti ipò rẹ̀, 2 Àwọn Ọba 19:15 sọ pé: “Ìwọ Jèhófà . . . , ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run tòótọ́.” (3) Ní ti ọlá àṣẹ rẹ̀, Ìṣípayá 4:11 sọ fún wa pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” (4) A tún gbọ́dọ̀ gbà pé Jèhófà ni Olùfúnni Ní Ìyè, ẹni tó pinnu láti gbà wá là lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú: “Ìgbàlà jẹ́ ti Jèhófà.” (Sáàmù 3:8; 36:9) (5) A ní láti gbà pé Jèhófà ni Olùfúnni Ní Òfin Gíga Jù Lọ: “Jèhófà ni Onídàájọ́ wa, Jèhófà ni Ẹni tí ń fún wa ní ìlànà àgbékalẹ̀, Jèhófà ni Ọba wa.” (Aísáyà 33:22) Nítorí pé òun ni gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn, a rọ̀ wá pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.”—Mátíù 22:37.
9. Kí ló túmọ̀ sí láti di ẹni tí a batisí “ní orúkọ . . . Ọmọ”?
9 Kí ni ìbatisí “ní orúkọ Ọmọ” túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí jíjẹ́wọ́ orúkọ Jésù Kristi àti títẹ́wọ́ gba ipò àti ọlá àṣẹ Mátíù 16:16; Kólósè 1:15, 16) Jòhánù 3:16 sọ fún wa ní ti Ọmọ yìí pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Nítorí pé Jésù ṣe olóòótọ́ títí dójú ikú, Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ó sì fi kún ọlá àṣẹ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti sọ, Ọlọ́run “gbé [Jésù] sí ipò gíga” ní ayé àtọ̀run, tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn Jèhófà, Jésù ló kàn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé “ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba . . . kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run Baba.” (Fílípì 2:9-11) Èyí túmọ̀ sí ṣíṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jésù, tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.—Jòhánù 15:10.
rẹ̀. Orúkọ rẹ̀, Jésù, túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà.” Ohun tó mú un wà ní ipò tó wà yìí ni jíjẹ́ tó jẹ́ Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run, ìyẹn àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá Ọlọ́run. (10. Kí ló túmọ̀ sí láti di ẹni tí a batisí “ní orúkọ . . . ẹ̀mí mímọ́”?
10 Kí ló túmọ̀ sí láti di ẹni tá a batisí “ní orúkọ . . . ẹ̀mí mímọ́”? Ó túmọ̀ sí fífaramọ́ ọ̀nà tí ẹ̀mí mímọ́ ń gbà ṣiṣẹ́ àtàwọn ìgbòkègbodò rẹ̀. Kí sì ni ẹ̀mí mímọ́ ọ̀hún? Ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ agbára ìṣiṣẹ́ Jèhófà, èyí tó ń lò láti ṣàṣeyọrí àwọn ète rẹ̀. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi yóò sì béèrè lọ́wọ́ Baba, yóò sì fún yín ní olùrànlọ́wọ́ mìíràn láti wà pẹ̀lú yín títí láé, ẹ̀mí òtítọ́ náà.” (Jòhánù 14:16, 17) Kí lèyí á ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe? Jésù tún sọ fún wọn pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, Jèhóf à tún mí sí kíkọ Bíbélì: “A kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípa ìfẹ́ ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.” (2 Pétérù 1:21) Nítorí náà, nígbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ńṣe là ń fi hàn pé a fara mọ́ ipa tí ẹ̀mí mímọ́ ń kó. Ọ̀nà mìíràn tá a tún ń gbà fi hàn pé a tẹ́wọ́ gba ẹ̀mí mímọ́ ni nípa bíbẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi àwọn “èso ti ẹ̀mí” hàn, èyí tí í ṣe “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.”—Gálátíà 5:22, 23.
11. (a) Kí ni ìjẹ́pàtàkì gidi tí ìbatisí ní lákòókò tiwa? (b) Báwo ni ìbatisí ṣe dà bí ìgbà téèyàn kú tá a sì jí i dìde?
11 Àwọn ẹni àkọ́kọ́ tí a batisí ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́ni Jésù ni àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù, bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 33, Sànmánì Tiwa. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tá a nawọ́ àǹfààní oníyebíye ti dídi Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn sí àwọn ará Samáríà. Lẹ́yìn náà, lọ́dún 36, Sànmánì Tiwa, ìpè náà wá gbòòrò sí i, ó nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́. Kí àwọn ará Samáríà àti àwọn Kèfèrí tó lè di ẹni tí a batisí, wọ́n ní láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, láti sìn ín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Ọmọ rẹ̀. Èyí ni ìjẹ́pàtàkì ìrìbọmi Kristẹni àní títí di àkókò tiwa yìí. Ríri ẹnì kan bọmi pátápátá jẹ́ àpẹẹrẹ tó ṣe wẹ́kú pé onítọ̀hún ya ara rẹ̀ sí mímọ́, èyí tá a lè fi wé sísin òkú. Rírì tá a rì ọ́ sísàlẹ̀ omi náà dúró fún pé o ti di òkú sí ìgbésí ayé tí ò ń gbé tẹ́lẹ̀. Gbígbé tí wọ́n gbé ọ jáde jẹ́ àmì pé a sọ̀ ọ́ di ààyè láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Gbogbo àwọn tó di Kristẹni tòótọ́ ló gbọ́dọ̀ ṣe “ìbatisí kan” yìí. Lákòókò ìrìbọmi, wọ́n di Kristẹni Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, àwọn òjíṣẹ́ tí Ọlọ́run ti fi àṣẹ yàn.—Éfésù 4:5; 2 Kọ́ríńtì 6:3, 4.
12. Kí ni ìrìbọmi Kristẹni ṣe rẹ́gí pẹ̀lú rẹ̀, lọ́nà wo sì ni?
1 Pétérù 3:21) Áàkì náà jẹ́ ẹ̀rí ńlá tó fi hàn pé Nóà ti fi ìṣòtítọ́ ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an. Lẹ́yìn tí iṣẹ́ kíkan ọkọ̀ náà parí, “ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀.” (2 Pétérù 3:6) Àmọ́ a gbé Nóà àti ìdílé rẹ̀ “la omi já láìséwu, èyíinì ni, ọkàn mẹ́jọ.”—1 Pétérù 3:20.
12 Lójú Ọlọ́run, irú ìbatisí bẹ́ẹ̀ ṣeyebíye gan-an fún rírí ìgbàlà. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù ti sọ nípa bí Nóà ṣe kan ọkọ̀ áàkì, nínú èyí tí òun àti ìdílé rẹ̀ fi di ẹni tí a pa mọ́ la Ìkún Omi náà já, ó kọ̀wé pé: “Èyíinì tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú èyí ni ó ń gbà yín là nísinsìnyí pẹ̀lú, èyíinì ni, ìbatisí, (kì í ṣe mímú èérí ara kúrò, bí kò ṣe ìbéèrè tí a ṣe sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún ẹ̀rí-ọkàn rere,) nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi.” (13. Nípasẹ̀ ìbatisí, a gba Kristẹni kan là kúrò lọ́wọ́ kí ni?
13 Lónìí, àwọn tó ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn nínú Kristi tí a jí dìde ń ṣe ìbatisí láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ yẹn hàn. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí a ṣe lọ́jọ́ òní, wọ́n sì ń di ẹni tí a gbà là kúrò nínú ayé búburú ìsinsìnyí. (Gálátíà 1:3, 4) Wọn ò tún bá ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí forí lé ọ̀nà ìparun mọ́. Ọlọ́run ti gbà wọ́n là lọ́wọ́ ìparun yìí ó sì fún wọn ní ẹ̀rí ọkàn rere. Àpọ́sítélì Jòhánù mú un dá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lójú pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17.
Ṣíṣe Ojúṣe Wa Dójú Àmì
14. Èé ṣe tí ìrìbọmi nìkan ṣoṣo kò mú ìgbàlà dájú?
14 Àṣìṣe gbáà ló máa jẹ́ láti ronú pé ìrìbọmi nìkan ló ń mú ìgbàlà ẹni dájú. Àyàfi téèyàn bá ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà tinútinú nípasẹ̀ Jésù Kristi tó sì ń bá a lọ láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, tó tún ṣe olóòótọ́ títí dópin, nìkan ni ìbatisí fi lè wúlò. “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.”—Mátíù 24:13.
15. (a) Kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run lónìí fún àwọn Kristẹni tó ti ṣe batisí? (b) Báwo ló ṣe yẹ kí jíjẹ́ Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn ṣe pàtàkì tó nínú ìgbésí ayé wa?
15 Ìfẹ́ Ọlọ́run fún Jésù kan bó ṣe lo ìgbésí ayé rẹ̀ nígbà tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn. Ó ní láti fi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ nínú ikú láti fi ṣe ìrúbọ. Ní tiwa, a ní láti fi ara wa fún Ọlọ́run, a sì gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti máa gbé ìgbésí ayé ìfara-ẹni-rúbọ nípa ṣíṣe ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. (Róòmù 12:1, 2) Ó dájú pé a ò ní í pè é ní ìfẹ́ Ọlọ́run bí a bá ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bí àwọn èèyàn ayé tó yí wá ka ṣe ń ṣe, ì báà ṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pàápàá, tàbí tí a bá jẹ́ kí lílépa ìfẹ́ tara wa gbà wá lọ́kàn, kó wá jẹ́ pé kìkì ìwọ̀nba iṣẹ́ ìsìn kíún là ń fún Ọlọ́run. (1 Pétérù 4:1-3; 1 Jòhánù 2:15, 16) Nígbà tí Júù kan béèrè ohun tí òun gbọ́dọ̀ ṣe láti ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́wọ́ Jésù, Jésù gbà pé gbígbé ìgbé ayé mímọ́ dára lóòótọ́. Àmọ́ ó tọ́ka sí ohun kan tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ: ìyẹn ni pé ó pọn dandan láti jẹ́ Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn, ẹni tó ń tẹ̀ lé Jésù. Èyí lohun tó gbọ́dọ̀ ṣe kókó jù lọ nínú ìgbésí ayé wa. A ò gbọ́dọ̀ fi lílépa àwọn ohun ìní ti ara ṣáájú rẹ̀.—Mátíù 19:16-21.
16. (a) Ẹrù iṣẹ́ wo la gbé lé gbogbo àwa Kristẹni lọ́wọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ìjọba náà? (b) Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ ní ojú ìwé 116 àti 117, àwọn ọ̀nà tó gbéṣẹ́ wo la lè gbà ṣe iṣẹ́ Ìjọba náà? (d) Tá a bá fi tọkàntọkàn nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà, ẹ̀rí kí ni ìyẹn jẹ́?
16 Lẹ́ẹ̀kan sí i, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé ìfẹ́ Ọlọ́run fún Jésù kan ṣíṣe iṣẹ́ pàtàkì tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run. Lóòótọ́ la ti fàmì òróró yan Jésù láti jẹ́ Ọba. Síbẹ̀, nígbà tó wà láyé, ó tún fi taratara jẹ́rìí nípa Ìjọba náà. Àwa pẹ̀lú ní irú iṣẹ́ ìjẹ́rìí bẹ́ẹ̀ láti ṣe, ó sì yẹ ká fi gbogbo ọkàn wa ṣe é. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni à ń fi ìmọrírì wa fún ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ àti ìfẹ́ tá a ní fún àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa hàn. (Mátíù 22:36-40) A tún ń fi hàn pé a wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn olùjọ́sìn ẹlẹgbẹ́ wa karí ayé, tí gbogbo wọn jẹ́ olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run. Ní ìṣọ̀kan karí ayé, à ń tẹ̀ síwájú lápapọ̀ láti lè jẹ́ kí ọwọ́ wa tẹ ìyè ayérayé lórí ilẹ̀ ayé níbí, tó jẹ́ ara ibi tí Ìjọba yẹn ń ṣàkóso lé lórí.
Àtúnyẹ̀wò fún Ìjíròrò
• Àwọn ìjọra àti ìyàtọ̀ wo ló wà nínú ìrìbọmi Jésù àti èyí tá à ń ṣe lónìí?
• Kí ló túmọ̀ sí láti batisí “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́”?
• Kí ni ṣíṣe ojúṣe tí ìrìbọmi Kristẹni ń béèrè fún dójú àmì wé mọ́?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwés 116, 117]
ÀWỌN Ọ̀NÀ KAN TÁ A LÈ GBÀ POLONGO ÌHÌN RERE NÁÀ
Láti ilé dé ilé
Fún àwọn ẹbí ẹni
Fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni
Fún àwọn ọmọléèwé ẹni
Ní òpópónà
Nípa pípadà lọ bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò
Níbi tá a ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì