Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Òmìnira Tí Àwọn Olùjọ́sìn Jèhófà Ń Gbádùn

Òmìnira Tí Àwọn Olùjọ́sìn Jèhófà Ń Gbádùn

Orí Karùn-ún

Òmìnira Tí Àwọn Olùjọ́sìn Jèhófà Ń Gbádùn

1, 2. (a) Irú òmìnira wo ni Ọlọ́run fún àwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́? (b) Sọ díẹ̀ lára àwọn òfin tó ń darí ìgbòkègbodò Ádámù àti Éfà.

NÍGBÀ tí Jèhófà dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, wọ́n gbádùn òmìnira táwọn èèyàn ò gbádùn irú rẹ̀ lónìí. Párádísè ni wọ́n ń gbé, ìyẹn Ọgbà Édẹ́nì ẹlẹ́wà. Àìsàn kankan kò ba ayọ̀ ìgbésí ayé wọn jẹ́, nítorí pé gbogbo ara wọn ló pé. Wọn ò retí pé àwọ́n máa kú lọ́jọ́ kan bí gbogbo èèyàn ṣe ń retí látìgbà náà wá. Bákan náà, wọn ò dà bí ẹ̀rọ tí à ń darí, àmọ́ wọ́n ní ẹ̀bùn òmìnira tó ga, ìyẹn ni pé wọ́n lè ṣe ìpinnu fúnra wọn. Àmọ́ tí wọ́n bá fẹ́ máa gbádùn òmìnira yìí lọ, wọ́n gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún àwọn òfin Ọlọ́run.

2 Bí àpẹẹrẹ, gbé àwọn òfin tó ṣeé fojú rí tí Ọlọ́run ṣe yẹ̀ wò. Lóòótọ́, àwọn òfin yìí lè máà sí lákọọ́lẹ̀, àmọ́ Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà lọ́nà tí kò fi ní í nira fún wọn rárá láti ṣègbọràn sí i. Tí ebi bá ń pa wọ́n, ó jẹ́ àmì pé ó yẹ kí wọ́n jẹun, òùngbẹ jẹ́ àmì pé ó yẹ kí wọ́n mu omi, wíwọ̀ oòrùn sì jẹ́ àmì pé àkókò tó láti lọ sùn. Jèhófà tún fún wọn níṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe. Bí òfin ni iṣẹ́ yẹn ṣe rí, torí pé yóò máa darí ohun tí wọ́n bá ń ṣe. Wọ́n á bí àwọn ọmọ, wọ́n á ṣàkóso lórí oríṣiríṣi àwọn nǹkan alààyè tó wà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n á sì sọ Párádísè náà di gbígbòòrò títí tó fi máa karí ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15) Òfin tí ń tuni lára tó sì ṣàǹfààní mà lèyí jẹ́ o! Ó jẹ́ kí wọ́n ní iṣẹ́ tí ń tẹ́ni lọ́rùn gan-an, èyí tó máa jẹ́ kí wọ́n lè lo ọpọlọ wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lọ́nà tó ṣàǹfààní. Bákan náà, wọ́n ní òmìnira rẹpẹtẹ láti pinnu ọ̀nà tó wù wọ́n láti gbà ṣe iṣẹ́ wọn. Kí ni wọ́n tún nílò jùyẹn lọ?

3. Ọ̀nà wo ni Ádámù àti Éfà ì bá gbà kọ́ bí wọ́n ṣe máa fọgbọ́n lo òmìnira wọn láti ṣe ìpinnu?

3 Lóòótọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run fún Ádámù àti Éfà ní àǹfààní láti ṣe ìpinnu fúnra wọn, èyí kò túmọ̀ sí pé rere ló máa gbẹ̀yìn ìpinnu èyíkéyìí tí wọ́n bá ti ṣe. Wọ́n gbọ́dọ̀ fi àǹfààní tí wọ́n ní láti ṣe ìpinnu mọ si ohun tí òfin Ọlọ́run àtàwọn ìlànà rẹ̀ fàyè gbà. Báwo ni wọ́n á ṣe kọ́ àwọn nǹkan yìí? Nípa títẹ́tí sí Ẹlẹ́dàá wọn àti kíkíyèsí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ni. Ọlọ́run fún Ádámù àti Éfà ní làákàyè tí wọ́n nílò láti fi àwọn nǹkan tí wọ́n ń kọ́ sílò. Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti dá wọn ní pípé, ohun tí yóò máa wá sọ́kàn wọn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìpinnu ni gbígbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ. Àní, wọ́n á rí i dájú pé àwọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ká ní lóòótọ́ ni wọ́n mọyì ohun tí Ọlọ́run ṣe fún wọn tí wọ́n sì fẹ́ múnú rẹ̀ dùn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27; Jòhánù 8:29.

4. (a) Ǹjẹ́ òfin tí Ọlọ́run fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n má jẹ nínú èso igi kan fi òmìnira wọn dù wọ́n? (b) Èé ṣe tí ohun tí Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ wọn yìí kò fi burú?

4 Ó tọ̀nà nígbà náà pé, Ọlọ́run yàn láti dán ìfọkànsìn wọn sí i wò níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Òun ló fún wọn ní ìyè, ó sì fẹ́ mọ̀ bóyá lóòótọ́ ni wọ́n ṣe tán láti wà ní ipò tó fi wọ́n sí. Jèhófà fún Ádámù ní àṣẹ yìí pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá Éfà, ó sọ fún un nípa òfin yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 3:2, 3) Ǹjẹ́ ìkàléèwọ̀ yìí fi òmìnira wọn dù wọ́n? Rárá o. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tó dára lóríṣiríṣi láti jẹ láìsí pé wọ́n ń jẹ èso igi kan yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:8, 9) Kò sóhun tó ní kí wọ́n má gbà pé Ọlọ́run ló ni ayé, nígbà tó kúkú jẹ́ pé òun náà ló dá a. Nítorí náà, ó ní ẹ̀tọ́ láti ṣe òfin níbàámu pẹ̀lú ohun tó fẹ́ táá sì ṣe aráyé láǹfààní.—Sáàmù 24:1, 10.

5. (a) Báwo ni Ádámù àti Éfà ṣe pàdánù òmìnira ológo tí wọ́n ní? (b) Kí ló rọ́pò òmìnira tí Ádámù àti Éfà ti ń gbádùn tẹ́lẹ̀, ìpalára wo lèyí sì ti ṣe fún wa?

5 Ṣùgbọ́n kí ló ṣẹlẹ̀? Áńgẹ́lì kan tí ó jẹ́ kí ìmọtara-ẹni-nìkan darí òun nípa wíwá ipò ọlá, ṣi òmìnira rẹ̀ lò, ó sì di Sátánì, èyí tó túmọ̀ sí “Alátakò.” Ó tan Éfà jẹ nípa ṣíṣèlérí ohun tó ta ko ìfẹ́ Ọlọ́run fún un. (Jẹ́nẹ́sísì 3:4, 5) Ádámù dára pọ̀ mọ́ Éfà wọ́n sì jọ rú òfin Ọlọ́run. Ohun tí kì í ṣe tiwọn tí wọ́n mú yìí ló jẹ́ kí wọ́n sọ òmìnira ológo wọn nù. Ẹ̀ṣẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso wọn, ikú sì tẹ̀ lé e gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sọ fún wọn pé ó máa rí. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ogún tí wọ́n fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn, èyí sì máa ń hàn nínú èrò ọkàn wọn láti ṣe ohun tó burú nígbà gbogbo. Ẹ̀ṣẹ̀ tún fa àìpé, èyí tó ń yọrí sí àrùn, ọjọ́ ogbó àti ikú. Ìfẹ́ láti máa ṣe ohun tó burú ṣáá, èyí tí Sátánì ń mú kó gogò sí i ti mú kí àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn kún fún ìkórìíra, ìwà ọ̀daràn, ìnilára àti ogun tó ti gba ẹ̀mí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn. Ẹ ò rí i pé ìyàtọ̀ ńlá gbáà lèyí jẹ́ sí òmìnira tí Ọlọ́run fún aráyé níbẹ̀rẹ̀!—Diutarónómì 32:4, 5; Jóòbù 14:1, 2; Róòmù 5:12; Ìṣípayá 12:9.

Ibi Tá A Ti Lè Rí Òmìnira

6. (a) Ibo la ti lè rí òmìnira gidi? (b) Irú òmìnira wo ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

6 Nítorí ìwà ibi tó wà káàkiri lónìí, kò yani lẹ́nu pé lójú méjèèjì làwọn èèyàn ń fẹ́ òmìnira tó pọ̀ sí i. Àmọ́ ibo gan-an la ti lè rí òmìnira gidi? Jésù sọ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:31, 32) Òmìnira yìí kì í ṣe irú èyí táwọn èèyàn ń retí láti rí nígbà tí wọ́n bá kọ alákòóso kan tàbí irú ìjọba kan sílẹ̀ tí wọ́n sì yan òmíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, òmìnira yìí ní í ṣe pẹ̀lú ohun náà gan-an tó fa ìṣòro èèyàn. Ohun tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni òmìnira kúrò nínú jíjẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jòhánù 8:24, 34-36) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé tí ẹnì kan bá di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi lóòótọ́, á bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn ìyípadà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ìyẹn ni ìdáǹdè gidi!

7. (a) Ọ̀nà wo la lè gbà dòmìnira lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nísinsìnyí? (b) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti lè ní òmìnira yẹn?

7 Èyí kò túmọ̀ sí pé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn Kristẹni tòótọ́ ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ohun tó ń tini dẹ́ṣẹ̀. Níwọ̀n bí wọ́n ti jogún ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n ṣì ń bá a jìjàkadì. (Róòmù 7:21-25) Àmọ́ bí ẹnì kan bá ń fi àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀, kò tún ní jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Ẹ̀ṣẹ̀ kò tún ní dà bí apàṣẹwàá fún un, èyí táá máa sọ fún un pé báyìí ni kó ṣe tá á sì máa ṣègbọràn láìjanpata. Kò ní há sínú ọ̀nà ìgbésí ayé kan tí kò nítumọ̀, tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò ní jẹ́ kó gbádùn mọ́. Yóò ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run nítorí pé a ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́ jì í lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ tó ní nínú ẹbọ Kristi. Ìfẹ́ láti dẹ́ṣẹ̀ lè máa dìde nínú rẹ̀, àmọ́ tí kò bá gbà fún un nítorí pé ó ń rántí àwọn ẹ̀kọ́ mímọ́ tí Jésù fi kọ́ni, ńṣe ló ń fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ kì í ṣe ọ̀gá òun mọ́.—Róòmù 6:12-17.

8. (a) Àwọn òmìnira wo ni ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ ń fún wa? (b) Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sí àwọn alákòóso ayé?

8 Ronú ná nípa àwọn òmìnira tí à ń gbádùn nítorí pé a jẹ́ Kristẹni. A ti dòmìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn àbájáde ìjọsìn èké, kúrò lọ́wọ́ gbígba ohun asán gbọ́ àti kúrò lọ́wọ́ jíjẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀. Àgbàyanu òtítọ́ nípa ipò tí àwọn òkú wà àti ìrètí àjíǹde ti sọ wá dòmìnira kúrò lọ́wọ́ bíbẹ̀rù ikú láìnídìí. Mímọ̀ pé Ìjọba òdodo ti Ọlọ́run máa tóó rọ́pò àwọn ìjọba èèyàn aláìpé ń sọ wá dòmìnira kúrò lọ́wọ́ àìnírètí. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10) Àmọ́ ṣá o, irú òmìnira bẹ́ẹ̀ kò ní ká má pa òfin mọ́ kò sì ní ká má bọ̀wọ̀ fún àwọn alákòóso.—Títù 3:1, 2; 1 Pétérù 2:16, 17.

9. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà fi ìfẹ́ ràn wá lọ́wọ́ láti gbádùn òmìnira tó ga jù lọ tó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn nísinsìnyí? (b) Báwo la ṣe lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání?

9 Jèhófà kó fi wá sílẹ̀ pé ká máa ṣe èyí-jẹ-èyí-ò-jẹ ní wíwá ọ̀nà tó dára jù lọ láti fi gbé ìgbésí ayé. Ó mọ bí òún ṣe dá wa, ó mọ ohun tó máa fún wa nítẹ̀ẹ́lọ́rùn gidi àtohun tó máa ṣàǹfààní fún wa títí ayé. Ó mọ irú ìrònú àti irú ìwà tó lè ba àjọṣe ẹnì kan pẹ̀lú Òun jẹ́. Ó tún mọ irú ìwà tó lè ba àjọṣe ẹnì kan àtàwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ́, bóyá kí irú ìwà bẹ́ẹ̀ má tiẹ̀ jẹ́ kẹ́ni yẹn lè dénú ayé tuntun pàápàá. Nínú ìfẹ́ rẹ̀, Jèhófà ń sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún wa nípasẹ̀ Bíbélì àti ètò àjọ rẹ̀ tá a lè fojú rí. (Máàkù 13:10; Gálátíà 5:19-23; 1 Tímótì 1:12, 13) Ọwọ́ wa ló wá kù sí láti lo òmìnira tí Ọlọ́run fún wa láti pinnu ohun tá a máa ṣe nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí. A ò ní dà bí Ádámù, tá a bá fi ohun tí Bíbélì sọ fún wa sọ́kàn, ìpinnu ọlọgbọ́n la ó máa ṣe. A ó fi hàn pé níní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà ni olórí àníyàn wa nígbèésí ayé wa.

Àwọn Kan Ń Wá Òmìnira Tó Yàtọ̀

10. Irú òmìnira wo làwọn kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wá lọ?

10 Nígbà míì, àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn mìíràn tó ti dàgbà pàápàá lè máa wò ó pé àwọn tún fẹ́ irú òmìnira mìíràn. Ó lè dà bí ẹni pé àwọn ohun iyì àtohun ẹ̀yẹ kan wà nínú ayé, bí wọ́n bá sì ṣe ń ronú nípa rẹ̀ láá túbọ̀ máa wù wọ́n láti ṣe nǹkan wọ̀nyí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò yẹ Kristẹni. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa rò pé àwọn ò ní lo oògùn olóró, àwọn ò ní mu ọtí àmujù tàbí ṣe àgbèrè. Àmọ́ wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn tí kì í ṣe Kristẹni tòótọ́ rìn, wọ́n á fẹ́ kí àwọn ẹni yẹn tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Wọ́n tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n máa hùwà bíi tàwọn yẹn.—3 Jòhánù 11.

11. Ibo ni ìtànjẹ láti ṣe ohun tó burú ti máa ń wá nígbà mìíràn?

11 Nígbà míì, ìtànjẹ láti lọ́wọ́ sí ìwà tí kò yẹ Kristẹni máa ń wá látọ̀dọ̀ ẹnì kan tó fẹnu lásán sọ pé òun ń sin Jèhófà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni kan ní ìjímìjí nìyẹn, ó sì lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tiwa náà. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sábà máa ń ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n rò pé ó máa fún àwọn ní ìgbádùn, àmọ́ àwọn nǹkan yẹn kò bá òfin Ọlọ́run mu. Wọ́n máa ń rọ àwọn ẹlòmíràn pé kí wọ́n “gbádùn” ara wọn. Wọ́n ‘ń ṣèlérí òmìnira nígbà tí àwọn fúnra wọn jẹ́ ẹrú ìdíbàjẹ́.’—2 Pétérù 2:19.

12. Àwọn àbájáde tó ń bani nínú jẹ́ wo ló máa ń kẹ́yìn híhu ìwà tó ta ko àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run?

12 Nǹkan tó máa ń tìdí ohun tí wọ́n rò pé ó jẹ́ òmìnira yìí wá kì í dára rárá, nítorí pé ńṣe ni wọ́n ń rú òfin Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ìbálòpọ̀ tí kò bófin mu lè yọrí sí ìdààmú ọkàn, àrùn, ikú, oyún téèyàn kò fẹ́, o sì tún lè tú ìgbéyàwó ká. (1 Kọ́ríńtì 6:18; 1 Tẹsalóníkà 4:3-8) Lílo oògùn olóró lè fa kéèyàn máa kanra, kó máa sọ kántankàntan, kí ojú máà ríran dáadáa, kí òòyì máa kọ́ni àti kéèyàn má lè mí délẹ̀. Ó lè mú kéèyàn máa ṣe ìrànǹrán, ó sì lè fa ikú. Ó lè di ohun tẹ́ni náà á sọ di bárakú, èyí sì lè sọ ẹni náà di ọ̀daràn níbi tó ti ń wá owó láti fi rà á. Àwọn ohun tó máa ń tìdí ọtí àmujù jáde náà kò yàtọ̀ sí ìwọ̀nyí rárá. (Òwe 23:29-35) Àwọn tó ń dá irú àṣà bẹ́ẹ̀ lè rò pé àwọn lómìnira, àmọ́ nígbà tí wọ́n bá fi máa mọ̀ pé àwọn ti di ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀, ọjọ́ á ti lọ. Ẹ ò rí i pé ọ̀gá burúkú gbáà ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́! Ríronú lórí ọ̀ràn yìí nísinsìnyí lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe bá ara wa nínú irú ipò yìí.—Gálátíà 6:7, 8.

Ibi Tí Ìṣòro Ti Máa Ń Bẹ̀rẹ̀

13. (a) Báwo ni àwọn ìfẹ́ ọkàn tó máa ń yọrí sí wàhálà ṣe sábàá máa ń bẹ̀rẹ̀? (b) Láti lè lóye ohun tí “ẹgbẹ́ búburú” jẹ́, ojú ìwòye ta la nílò? (d) Bó o ṣe ń dáhùn àwọn ìbéèrè inú ìpínrọ̀ 13, sọ ọ̀nà tí ohun tó jẹ́ ojú ìwòye Jèhófà gbà ṣe pàtàkì.

13 Ronú nípa ibi tí ìṣòro ti sábà máa ń bẹ̀rẹ̀. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀; ẹ̀wẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti ṣàṣeparí rẹ̀, a mú ikú wá.” (Jákọ́bù 1:14, 15) Báwo ni ìfẹ́ yẹn ṣe máa ń dìde nínú ọkàn? Nípasẹ̀ ohun tó ń wọ inú ọpọlọ ni. Lọ́pọ̀ ìgbà, èyí máa ń ṣẹlẹ̀ nípa bíbá àwọn èèyàn tí kò fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò kẹ́gbẹ́. Ó dájú pé, gbogbo wa la mọ̀ pé ó yẹ ká yàgò fún “ẹgbẹ́ búburú.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Àmọ́ àwọn ẹgbẹ́ wo ló burú? Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ọ̀ràn yìí? Ríronú lórí àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí àti gbígbé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ yẹ̀ wò á ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tó tọ́.

Ṣé torí pé àwọn èèyàn kan dà bí ẹni iyì túmọ̀ sí pé wọ́n jẹ́ ẹni dáadáa láti bá kẹ́gbẹ́? (Jẹ́nẹ́sísì 34:1, 2, 18, 19)

Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wọn tàbí àpárá tí wọ́n máa ń dá tiẹ̀ fi hàn pé irú wọn ló yẹ ká máa bá ṣe wọlé-wọ̀de? (Éfésù 5:3, 4)

Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tó bá jẹ́ pé àwọn èèyàn tí kò fẹ́ràn rẹ̀ la yàn ní kòríkòsùn wa? (2 Kíróníkà 19:1, 2)

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè máa bá àwọn èèyàn tí kò gba ohun kan náà gbọ́ pẹ̀lú wa ṣiṣẹ́ pọ̀ tàbí ká jọ máa lọ síléèwé kan náà, ìdí wo la fi gbọ́dọ̀ ṣọ́ra? (1 Pétérù 4:3, 4)

Wíwo tẹlifíṣọ̀n àti sinimá, lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì àti kíka àwọn ìwé títí kan ìwé ìròyìn jẹ́ àwọn ọ̀nà tá a fi ń bá àwọn mìíràn kẹ́gbẹ́. Irú àwọn nǹkan wo tó ń wá láti orísun yìí ló yẹ ká ṣọ́ra fún? (Òwe 3:31; Aísáyà 8:19; Éfésù 4:17-19)

Kí ni irú àwọn tí à ń bá kẹ́gbẹ́ ń sọ fún Jèhófà nípa irú èèyàn tá a jẹ́? (Sáàmù 26:1, 4, 5; 97:10)

14. Òmìnira kíkọyọyọ wo ló ń dúró de àwọn tó bá fi òótọ́ inú fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò?

14 Ayé tuntun Ọlọ́run ti wọlé dé. Nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run, aráyé á bọ́ lọ́wọ́ ìdarí Sátánì àti gbogbo ètò àwọn nǹkan rẹ̀ pátá. Díẹ̀díẹ̀, gbogbo ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ ti fà ni a óò mú kúrò lára àwọn èèyàn onígbọràn, èyí táá yọrí sí ìjẹ́pípé èrò inú àti ara, tí yóò sì mú kó ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn ìyè ayérayé nínú Párádísè. Níkẹyìn, gbogbo ẹ̀dá pátá yóò gbádùn òmìnira tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú “ẹ̀mí Jèhófà.” (2 Kọ́ríńtì 3:17) Ṣé ó wá bọ́gbọ́n mu láti pàdánù gbogbo nǹkan yìí nítorí àìka ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí nísinsìnyí? Nípa lílo òmìnira Kristẹni wa lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání lónìí, ǹjẹ́ kí gbogbo wa fi hàn lọ́nà tó ṣe kedere pé lóòótọ́ la fẹ́ “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:21.

Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò

• Irú òmìnira wo ni tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ gbádùn? Báwo ni ohun tí ojú aráyé ń kàn báyìí ṣe yàtọ̀ sí òmìnira yẹn?

• Irú òmìnira wo láwọn Kristẹni tòótọ́ ní? Báwo ni ìyẹn ṣe yàtọ̀ ní ìfiwéra pẹ̀lú ohun tí ayé kà sí òmìnira?

• Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì púpọ̀ pé ká yẹra fún ẹgbẹ́ búburú? Láìdàbí Ádámù, ìpinnu ta ni à ń tẹ̀ lé láti mọ̀ bóyá ohun kan burú?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 46]

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́”