Ẹ Máa Fi Àìṣojo Sọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Orí Kọkàndínlógún
Ẹ Máa Fi Àìṣojo Sọ̀rọ̀ Ọlọ́run
1. (a) Ìhìn rere wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù polongo, àmọ́ ọwọ́ wo làwọn Júù kan fi mú ọ̀ràn náà? (b) Àwọn ìbéèrè wo la lè béèrè?
NǸKAN bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn la fòróró yan Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí Ọba-lọ́la lórí gbogbo ilẹ̀ ayé. Àwọn ẹlẹ́sìn tó jẹ́ ọ̀tá Jésù ṣekú pa á, àmọ́ Jèhófà jí i dìde kúrò nínú òkú. Ìyè àìnípẹ̀kun wá ṣeé ṣe báyìí nípasẹ̀ Jésù. Àmọ́ inúnibíni tún dìde nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bẹ̀rẹ̀ sí polongo ìhìn rere yìí ní gbangba. Wọ́n ju àwọn kan lára wọn sẹ́wọ̀n, kódà wọ́n nà wọ́n lẹ́gba, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn láti dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa Jésù. (Ìṣe 4:1-3, 17; 5:17, 18, 40) Kí ni kí wọ́n ṣe? Ká ní ìwọ ni, kí lò bá ṣe? Ṣé ò bá máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ láìṣojo?
2. (a) Ìhìn àgbàyanu wo ló yẹ ká pòkìkí rẹ̀ lákòókò tá a wà yìí? (b) Àwọn wo ni ẹrù iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà já lé léjìká?
2 Ní ọdún 1914, Jésù Kristi, Ọba Ìjọba Ọlọ́run gorí ìtẹ́ lọ́run láti máa ṣàkóso ‘láàárín àwọn ọ̀tá rẹ̀.’ (Sáàmù 110:2) Ẹ̀yìn ìyẹn ló fi Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 12:1-5, 7-12) Àtìgbà yẹn ni ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí ti bẹ̀rẹ̀. Ìgbà tí àkókò yìí bá dópin, Ọlọ́run yóò fọ́ gbogbo ètò nǹkan Sátánì túútúú. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 24:21) Àwọn tó bá là á já yóò wá fojú sọ́nà fún ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé tó máa di Párádísè. Tó o bá ti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere yìí, wàá fẹ́ sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa rẹ̀. (Mátíù 24:14) Àmọ́, báwo lo ṣe rò pé wọ́n máa dáhùn padà?
3. (a) Báwo làwọn èèyàn ṣe máa ń dáhùn sí ìhìn Ìjọba náà? (b) Àwọn ìbéèrè wo la gbọ́dọ̀ dojú kọ?
3 Nígbà tó o bá ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, àwọn kan lè tẹ́wọ́ gbà á, àmọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ ni kò ní kà á kún. (Mátíù 24:37-39) Àwọn kan lè fi ọ́ ṣẹ̀sín tàbí kí wọ́n lòdì sí ọ. Jésù kìlọ̀ pé àtakò lè wá látọ̀dọ̀ àwọn ìbátan rẹ pàápàá. (Lúùkù 21:16-19) Àtakò tiẹ̀ lè dìde níbi iṣẹ́ rẹ tàbí nílé ìwé. Ìjọba tiẹ̀ ti fòfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn apá ibì kan lórí ilẹ̀ ayé. Bó o bá wà nírú ipò yẹn, ṣé wàá máa bá a lọ láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìṣojo, kó o sì “dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́”?—1 Kọ́ríńtì 16:13.
A Kò Gbara Lé Okun Ti Ara Wa
4. (a) Láti fi hàn pé a jẹ́ ìránṣẹ́ tòótọ́ fún Ọlọ́run, kí ni ohun ìpìlẹ̀ tí a béèrè? (b) Kí nìdí táwọn ìpàdé Kristẹni fi ṣe pàtàkì gan-an?
4 Ohun tó ṣe pàtàkì jù láti jẹ́ ìránṣẹ́ tòótọ́ fún Jèhófà ni gbígbára lé àwọn ohun tó pèsè fún ire tẹ̀mí wa. Ọ̀kan lára ìwọ̀nyí ni àwọn ìpàdé ìjọ. Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú láti má ṣe fọwọ́ yẹpẹrẹ mú wọn. (Hébérù 10:23-25) Àwọn tó ń bá a lọ láti jẹ́ Ẹlẹ́rìí tòótọ́ fún Jèhófà ti sa gbogbo ipá wọn láti máa bá àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn ṣèpàdé déédéé. Inú àwọn ìpàdé wọ̀nyí ni ìmọ̀ tá a ní nípa Ìwé Mímọ́ ti ń pọ̀ sí i. Bákan náà là ń lóye òtítọ́ sí i, a sì túbọ̀ ń mọ àwọn ọ̀nà tá a lè gbà lò wọ́n. A túbọ̀ ń sún mọ́ àwọn Kristẹni arákùnrin wa nínú ìjọsìn tó ṣọ̀kan, ìyẹn sì ń fún wa lókun láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ẹ̀mí Jèhófà ń tipasẹ̀ ìjọ darí wa, Jésù sì tipasẹ̀ ẹ̀mí yẹn wà láàárín wa.—Mátíù 18:20; Ìṣípayá 3:6.
5. Nígbà tá a bá fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí ni wọ́n máa ń ṣe nípa àwọn ìpàdé?
5 Ṣé o máa ń lọ sí gbogbo ìpàdé déédéé, ṣé o sì máa ń fi àwọn ohun tó ò ń gbọ́ níbẹ̀ sílò? Nígbà mìíràn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá wà lábẹ́ ìfòfindè, ó pọn dandan fún wọn láti ṣe àwọn ìpàdé ní àwùjọ kéékèèké láwọn ilé àdáni. Àwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣe é àti àkókò tí wọ́n ń ṣe é lè yàtọ̀ síra, kì í sì í fi gbogbo ìgbà rọrùn, kódà wọ́n máa ń ṣe àwọn ìpàdé mìíràn lóru. Ṣùgbọ́n láìfi bí nǹkan kò ṣe rọrùn tàbí ewu tó wà pè, àwọn arákùnrin àti arábìnrin olùṣòtítọ́ ń sa gbogbo ipá wọn láti pésẹ̀ sí ìpàdé kọ̀ọ̀kan.
6. Báwo la ṣe ń fi hàn pé a gbára lé Jèhófà, báwo lèyí sì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa sọ̀rọ̀ láìṣojo?
6 Gbígbáralé Jèhófà ni à ń mú dàgbà nípa yíyíjú sí i déédéé nínú àdúrà àtọkànwá, tó ń fi hàn pé a nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ò ń ṣèyẹn? Jésù gbàdúrà léraléra nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 3:21; 6:12, 13; 22:39-44) Ní alẹ́ tó ṣáájú ìgbà tí wọ́n kàn án mọ́gi, ó rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, kí ẹ má bàa wá sínú ìdẹwò.” (Máàkù 14:38) Tá a bá rí i pé àwọn èèyàn ń dágunlá sí ìhìn Ìjọba náà, ìyẹn lè fẹ́ mú wa dẹwọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Báwọn èèyàn bá ń fi wá ṣẹ̀sín tàbí tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká dáwọ́ ìwàásù wa dúró ká lè bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro. Àmọ́ bá a bá ń gbàdúrà pé kí ẹ̀mí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ láti máa sọ̀rọ̀ láìṣojo, a ò ní tìtorí àwọn ìdẹwò wọ̀nyẹn juwọ́ sílẹ̀.—Lúùkù 11:13; Éfésù 6:18-20.
Àkọsílẹ̀ Nípa Jíjẹ́rìí Láìṣojo
7. (a) Èé ṣe tí àkọsílẹ̀ inú ìwé Ìṣe fi fà wá lọ́kàn mọ́ra gan-an? (b) Dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà ní òpin ìpínrọ̀ yìí, kí o sì sọ bí ìsọfúnni náà ṣe lè ṣe wá láǹfààní.
7 Àkọsílẹ̀ tó wà nínú ìwé Ìṣe fà wá lọ́kàn mọ́ra gan-an. Ó sọ nípa bí àwọn àpọ́sítélì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀—ìyẹn àwọn tó ní ìmọ̀lára bíi tiwa—ṣe borí àwọn ìdènà, tí wọ́n sì fi hàn pé ẹlẹ́rìí tí kì í ṣojo, tó sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà làwọn. Ẹ jẹ́ ká fi àwọn ìbéèrè àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí yẹ apá kan àkọsílẹ̀ yẹn wo. Bí a ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, máa ronú nípa bí ìwọ fúnra rẹ ṣe lè jàǹfààní látinú ohun tó ò ń kà.
Ṣé àwọn tó kàwé gíga láwọn àpọ́sítélì? Ṣé ẹ̀dá tí kì í bẹ̀rù ni wọ́n láìka ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀ sí? (Jòhánù 18:17, 25-27; 20:19; Ìṣe 4:13)
Kí ló ran Pétérù lọ́wọ́ láti fi àìṣojo sọ̀rọ̀ níwájú ilé ẹjọ́ àwọn Júù tó dá Ọmọ Ọlọ́run lẹ́bi? (Mátíù 10:19, 20; Ìṣe 4:8)
Kí làwọn àpọ́sítélì ń ṣe láwọn ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú ìgbà tá a mú wọn wá síwájú Sànhẹ́dírìn? (Ìṣe 1:14; 2:1, 42)
Nígbà táwọn alákòóso pàṣẹ fáwọn àpọ́sítélì láti dẹ́kun wíwàásù ní orúkọ Jésù, báwo ni Pétérù àti Jòhánù ṣe fèsì? (Ìṣe 4:19, 20)
Lẹ́yìn tí wọ́n tú àwọn àpọ́sítélì sílẹ̀, ta ni wọ́n tún padà yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́? Ǹjẹ́ wọ́n gbàdúrà pé kí inúnibíni náà dáwọ́ dúró, àbí kí ni wọ́n gbàdúrà fún? (Ìṣe 4:24-31)
Kí ni Jèhófà lò láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà táwọn alátakò Ìṣe 5:17-20)
ń gbìyànjú láti dá iṣẹ́ ìwàásù náà dúró? (Báwo làwọn àpọ́sítélì ṣe fi hàn pé àwọn mọ ìdí tí wọ́n fi dá wọn nídè? (Ìṣe 5:21, 41, 42)
Kódà nígbà tí ọ̀pọ̀ ọmọ ẹ̀yìn fọ́n ká nítorí inúnibíni, kí ni wọ́n ń bá a lọ láti máa ṣe? (Ìṣe 8:3, 4; 11:19-21)
8. Kí ni àbájáde amúnilọ́kànyọ̀ tó tinú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ jáde, báwo làwa náà sì ṣe dẹni tó ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan náà?
8 Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà kò já sí asán. Nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọmọ ẹ̀yìn ló ṣe batisí ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. “Àwọn onígbàgbọ́ nínú Olúwa [ń] kún wọn ṣáá, ògìdìgbó lọ́kùnrin àti lóbìnrin.” (Ìṣe 2:41; 4:4; 5:14) Bí àkókò ti ń lọ, kódà Sọ́ọ̀lù ará Tásù, tó ṣe inúnibíni gbígbóná janjan sáwọn ènìyàn Ọlọ́run, di Kristẹni, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àìṣojo jẹ́rìí sí òtítọ́. Òun la wá mọ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. (Gálátíà 1:22-24) Iṣẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní náà kò tíì dáwọ́ dúró. Ó ti gbèrú gan-an ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, ó sì ti dé apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé. A láǹfààní láti kópa nínú rẹ̀, bí a sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, a lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ tí àwọn ẹlẹ́rìí olóòótọ́ tó ti sìn ṣáájú wa fi lélẹ̀.
9. (a) Àwọn àǹfààní wo ni Pọ́ọ̀lù lò láti jẹ́rìí? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni ìwọ náà ń gbà sọ ìhìn Ìjọba náà fún àwọn ẹlòmíràn?
9 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jésù Kristi, kí ló ṣe? “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù Jésù . . . , pé Ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.” (Ìṣe 9:20) Ó mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fi hàn sí i, ó sì mọ̀ pé gbogbo èèyàn ló nílò ìhìn rere tí òun ti rí gbà náà. Júù ni Pọ́ọ̀lù, gẹ́gẹ́ bí àṣà tó sì wà nígbà yẹn, ó lọ sínú àwọn sínágọ́gù láti jẹ́rìí. Ó tún wàásù láti ilé dé ilé, ó sì fèrò wérò pẹ̀lú àwọn tó wà níbi ọjà. Ó sì múra tán láti lọ wàásù ìhìn rere náà láwọn ìpínlẹ̀ tuntun.—Ìṣe 17:17; 20:20; Róòmù 15:23, 24.
10. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé bí òun kò tilẹ̀ ṣojo, síbẹ̀ òun jẹ́ olóye nínú ọ̀nà tó gbà jẹ́rìí? (b) Báwo la ṣe lè gbé àwọn ànímọ́ Pọ́ọ̀lù yọ nígbà tá a bá ń jẹ́rìí fáwọn ìbátan, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, tàbí àwọn ọmọ ilé ìwé wa?
10 Pọ́ọ̀lù jẹ́ onígboyà, ó sì tún jẹ́ olóye, bó ṣe yẹ kí àwa náà jẹ́. Ó bá àwọn Júù sọ̀rọ̀ nípa gbígbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ka orí àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba ńlá wọn. Ó sì bá àwọn Gíríìkì sọ̀rọ̀ lórí ohun tí wọ́n mọ̀ dáadáa. Nígbà mìíràn, ó máa ń lò ìrírí tóun fúnra rẹ̀ ní nígbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láti fi jẹ́rìí fún àwọn èèyàn. Ó sọ pé: “Mo ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè di alájọpín nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.”—1 Kọ́ríńtì 9:20-23; Ìṣe 22:3-21.
11. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe láti yàgò fún fífi gbogbo ìgbà bá àwọn alátakò ṣàròyé? (b) Ìgbà wo la lè fọgbọ́n fara wé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, lọ́nà wo sì ni? (d) Ibo ni agbára láti máa sọ̀rọ̀ láìṣojo ti ń wá?
11 Nígbà tí àtakò jẹ́ kó dà bíi pé ó sàn kí Pọ́ọ̀lù lọ wàásù ní àgbègbè mìíràn fúngbà díẹ̀, ó ṣe bẹ́ẹ̀ dípò tí ì bá fi máa bá àwọn alátakò ṣàròyé ní gbogbo ìgbà. (Ìṣe 14:5-7; 18:5-7; Róòmù 12:18) Àmọ́, kò fìgbà kan tijú ìhìn rere náà. (Róòmù 1:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà àfojúdi—kódà ìwà òǹrorò—táwọn alátakò ń hù sí Pọ́ọ̀lù kò rọrùn fún un láti fara dà, síbẹ̀ ó “máyàle nípasẹ̀ Ọlọ́run wa” láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà nìṣó. Ó sọ pé: “Olúwa dúró lẹ́bàá mi, ó sì fi agbára sínú mi, pé nípasẹ̀ mi, kí a lè ṣàṣeparí ìwàásù náà ní kíkún.” (1 Tẹsalóníkà 2:2; 2 Tímótì 4:17) Jésù, tó jẹ́ Orí ìjọ Kristẹni, ń bá a lọ láti pèsè agbára tá a nílò láti ṣe iṣẹ́ tó sọ tẹ́lẹ̀ fún ọjọ́ wa.—Máàkù 13:10.
12. Kí ló ń fi àìṣojo Kristẹni hàn, kí sì nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?
12 Kò sídìí tí kò fi yẹ ká máa bá a lọ láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìṣojo, gẹ́gẹ́ bíi Jésù àtàwọn mìíràn tó jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti ṣe ní ọ̀rúndún kìíní. Èyí kò wá túmọ̀ sí pé a ò ní gba tàwọn ẹlòmíràn rò, tàbí ká máa gbìyànjú láti fi tipátipá sọ ìhìn náà fún àwọn tí kò fẹ́ gbọ́. Àmọ́ a ò ní tìtorí pé àwọn èèyàn ń dágunlá, ká wá juwọ́ sílẹ̀; bẹ́ẹ̀ náà la ò ní jẹ́ kí àtakò mú wa dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ. Bíi ti Jésù, à ń tọ́ka sí Ìjọba Ọlọ́run pé ó jẹ́ ìjọba tó dára jù lọ fún gbogbo ilẹ̀ ayé. À ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú, nítorí pé Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run là ń ṣojú fún àti nítorí pé àtọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìhìn tá à ń polongo náà ti wá, kì í ṣe látọ̀dọ̀ wa. Ìfẹ́ wa fún Jèhófà ló sì gbọ́dọ̀ jẹ́ olórí ohun tó ń mú wa yìn ín.—Fílípì 1:27, 28; 1 Tẹsalóníkà 2:13.
Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti sọ ìhìn Ìjọba náà fún gbogbo ẹni tó bá ṣeé ṣe láti sọ ọ́ fún, àmọ́ àwọn ìṣesí wo la lè retí?
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a kò gbára lé okun ti ara wa láti sin Jèhófà?
• Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ nínú ìwé Ìṣe?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 173]
Bó ṣe rí láyé ọjọ́un, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní ń fi àìṣojo sọ̀rọ̀ Ọlọ́run