Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Ní Ìfẹ́ Gbígbóná Janjan fún Ara Yín”

“Ẹ Ní Ìfẹ́ Gbígbóná Janjan fún Ara Yín”

Orí Kẹrìndínlógún

“Ẹ Ní Ìfẹ́ Gbígbóná Janjan fún Ara Yín”

1. Kí ló sábà máa ń wú àwọn ẹni tuntun tó bá wá sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí?

TÍ ÀWỌN èèyàn bá wá sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ìgbà àkọ́kọ́, ìfẹ́ tí a máa ń fi hàn níbẹ̀ sábà máa ń wú wọn lórí. Wọ́n máa ń rí i pé a fi ọ̀yàyà kí àwọn àti pé ìfararora tó dùn mọ́ni wà níbẹ̀. Àwọn tó ń wá wo àwọn àpéjọ wa náà ń ṣàkíyèsí ìfẹ́ yìí pẹ̀lú. Akọ̀ròyìn kan kọ̀wé nípa àpéjọ àgbègbè wa pé: ‘Ẹnikẹ́ni ò hùwà bí ajoògùnyó tàbí ọ̀mùtí. Kò sáriwo tàbí igbe. Ẹnì kan ò ti ẹnì kejì. Kò sẹ́ni tó ń taari ẹlòmíràn. Èébú ò wáyé bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́ni tó ṣépè. Ẹnikẹ́ni ò sọ àsé ọ̀rọ̀ tàbí ìsọkúsọ. Kò sí òórùn sìgá rárá. Kò sí olè jíjà. Wọn ò sọ agolo ọtí sílẹ̀ káàkiri ibẹ̀. Áà, èyí yàtọ̀ gbáà.’ Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé a ní ìfẹ́, èyí tó jẹ́ pé “kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.”—1 Kọ́ríńtì 13:4-8.

2. (a) Bí a ṣe ń tẹ̀ síwájú, kí ló yẹ kí ó máa hàn ní ti bá a ṣe ń fi ìfẹ́ hàn? (b) Irú ìfẹ́ wo ló yẹ ká fi kọ́ra ní àfarawé Kristi?

2 Ìfẹ́ ará ni àmì tí a fi ń dá àwọn ojúlówó Kristẹni mọ̀. (Jòhánù 13:35) Bí a ṣe túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú sí i nípa tẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe túbọ̀ máa mọ bí a ṣe ń fi ìfẹ́ hàn ní kíkún. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbàdúrà pé kí ìfẹ́ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ “túbọ̀ máa pọ̀ gidigidi síwájú àti síwájú.” (Fílípì 1:9) Àpọ́sítélì Jòhánù fi hàn pé ìfẹ́ wa ní láti jẹ́ ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ. Ó kọ̀wé pé: “Nípa èyí ni àwa fi wá mọ ìfẹ́, nítorí [Ọmọ Ọlọ́run] fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ fún wa; a sì wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti fi ọkàn wa lélẹ̀ fún àwọn arákùnrin wa.” (1 Jòhánù 3:16; Jòhánù 15:12, 13) Ṣé a lè fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ nítorí àwọn ará wa lóòótọ́? Òótọ́ ni pé ọ̀ràn tó lè sún wa ṣe bẹ́ẹ̀ kò wọ́pọ̀, ṣùgbọ́n báwo la ṣe ń làkàkà tó láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ará wa nísinsìnyí, pàápàá nígbà tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ò bá rọrùn fún wa?

3. (a) Ọ̀nà wo ni a tún lè gbà fi ìfẹ́ wa hàn ní kíkún sí i? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ní ìfẹ́ tó gbóná janjan fún ara wa nísinsìnyí?

3 Bí a ṣe ń lo ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ, ó tún yẹ ká máa fi ojúlówó ẹ̀mí ọ̀yàyà hàn sí àwọn ará wa pẹ̀lú. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé: “Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Róòmù 12:10) Kò sẹ́ni tí kò ní àwọn èèyàn kan tó máa ń fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn sí. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ a lè fi kọ́ra láti tún máa yá mọ́ àwọn mìíràn sí i? Bí òpin ètò ògbólógbòó yìí ṣe ń sún mọ́lé, ó ṣe pàtàkì pé ká túbọ̀ fà mọ́ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa. Bíbélì sọ pé: “Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé. . . . Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”—1 Pétérù 4:7, 8.

Nígbà Tí Ìṣòro Bá Yọjú

4. (a) Kí nìdí tí ìṣòro fi lè jẹ yọ láàárín àwọn ará inú ìjọ? (b) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà mìíràn ó lè má dùn mọ́ wa láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì, síbẹ̀ bí a bá fi í sílò ire wo ni yóò ṣe?

4 Àmọ́ ṣá o, níwọ̀n ìgbà tí a ṣì jẹ́ aláìpé, àwọn ìgbà kan á máa wà tí a óò ṣe ohun tó ń bí ẹlòmíràn nínú. Àwọn ará wa sì lè ṣẹ̀ wá lónírúurú ọ̀nà pẹ̀lú. (1 Jòhánù 1:8) Bí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ọ kí ló yẹ kó o ṣe? Ìwé Mímọ́ fún wa ní ìtọ́sọ́nà tí a nílò. Ṣùgbọ́n ohun tí Ìwé Mímọ́ wí lè máà bá ohun tí àwa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá aláìpé máa fẹ́ láti ṣe mu. (Róòmù 7:21-23) Àmọ́, bí a bá làkàkà láti fi ìmọ̀ràn inú Bíbélì sílò, yóò jẹ́ ẹ̀rí pé tọkàntọkàn là ń fẹ́ láti wu Jèhófà. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò sì tún mú kí ìfẹ́ wa fún ọmọnìkejì wa jinlẹ̀ sí i.

5. Bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá kí nìdí tí kò fi yẹ ká gbẹ̀san?

5 Tí ohun tẹ́nì kan ṣe bá dun àwọn èèyàn, wọ́n sábà máa ń wá ọ̀nà láti gbẹ̀san. Ṣùgbọ́n ńṣe nìyẹn kàn túbọ̀ ń mú kí ọ̀ràn náà burú sí i. Bó bá ṣe wá bíi pé ká gbẹ̀san, ẹ jẹ́ ká fi ọ̀ràn lé Ọlọ́run lọ́wọ́. (Òwe 24:29; Róòmù 12:17-21) Àwọn mìíràn tiẹ̀ lè gbìyànjú láti máa yẹra fún ẹni tó ṣẹ̀ wọ́n ọ̀hún. Ṣùgbọ́n kò yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ sáwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa, nítorí kí ìsìn wa tó lè ní ìtẹ́wọ́gbà, dandan ni ká kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa. (1 Jòhánù 4:20) Ìyẹn ni Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.” (Kólósè 3:13) Ǹjẹ́ o lè ṣe bẹ́ẹ̀?

6. (a) Báwo ló ṣe yẹ ká máa dárí ji arákùnrin wa lemọ́lemọ́ tó? (b) Láti lè mọ ohun tó yẹ láti ṣe tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá, kí ló yẹ ká máa rántí pé àwa náà ń ṣe?

6 Ká wá sọ pé ẹnì kan ń ṣẹ̀ wá léraléra ṣùgbọ́n kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tó fi lè dẹni tá a yọ kúrò nínú ìjọ ń kọ́? Ní ti irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké bẹ́ẹ̀, àpọ́sítélì Pétérù dábàá pé kí á dárí jì í “títí dé ìgbà méje.” Ṣùgbọ́n Jésù sọ pé: “Kì í ṣe, Títí dé ìgbà méje, bí kò ṣe, Títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.” Ó wá mú àlàyé ṣe nípa bí gbèsè tí a jẹ Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó ní ìfiwéra pẹ̀lú èyí tọmọ èèyàn èyíkéyìí lè jẹ wá. (Mátíù 18:21-35) Onírúurú ọ̀nà là ń gbà ṣẹ Ọlọ́run lójoojúmọ́, yálà nípa híhùwà ìmọtara-ẹni-nìkan, nípa ọ̀rọ̀ ẹnu wa tàbí èrò wa, tàbí nípa ohun tí a kùnà láti ṣe, láìtiẹ̀ ní mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ là ń dá. (Róòmù 3:23) Síbẹ̀, Ọlọ́run ń bá a lọ láti máa ṣàánú wa. (Sáàmù 103:10-14; 130:3, 4) Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni Ọlọ́run ní kí àwa náà máa ṣe sí ọmọnìkejì wa. (Mátíù 6:14, 15; Éfésù 4:1-3) Bí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ a jẹ́ pé à ń lo ìfẹ́ tí “kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.”—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5; 1 Pétérù 3:8, 9.

7. Kí ló yẹ ká ṣe bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ń bínú sí wa?

7 Àwọn ìgbà mìíràn lè wà tá a máa rí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú wa mọ́ sí arákùnrin tàbí arábìnrin kan, síbẹ̀ inú rẹ̀ kò yọ́ sí wa. Kí wá la lè ṣe? A lè jẹ́ kí ‘ìfẹ́ bo ọ̀rọ̀ yẹn mọ́lẹ̀’ bí 1 Pétérù 4:8 ṣe gbà wá nímọ̀ràn pé ká ṣe. Tàbí ká lo ìdánúṣe láti bá ẹni náà sọ̀rọ̀ láti tún àárín àwa àti onítọ̀hún ṣe.—Mátíù 5:23, 24.

8. Bí onígbàgbọ́ bíi tiwa bá ń ṣe ohun tó ń bí wa nínú, kí la lè ṣe nípa rẹ̀?

8 Ó lè ṣẹlẹ̀ pé onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ kan ń ṣe nǹkan kan tó jẹ́ pé, yàtọ̀ sí pé ó ń bí ọ nínú, ó tún ń bí àwọn mìíràn nínú pẹ̀lú. Ǹjẹ́ kò ní dáa ká bá a sọ̀rọ̀? Ìyẹn lè dáa. Bí o bá fúnra rẹ ṣàlàyé ọ̀ràn yẹn fún un pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, ó ṣeé ṣe kí ó ṣàtúnṣe. Ṣùgbọ́n ó yẹ kó o kọ́kọ́ bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ohun tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ló ń ṣe lóòótọ́? Tàbí ohun tó fà á ni pé àṣà ibi ti mo gbé dàgbà àti bí wọ́n ṣe tọ́ mi dàgbà yàtọ̀ sí tiẹ̀?’ Ṣọ́ra kó o má ṣe gbé ìlànà tìrẹ kalẹ̀ kó o sì máa wá lò ó láti fi dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́. (Jákọ́bù 4:11, 12) Jèhófà a máa tẹ́wọ́ gba àwọn èèyàn onírúurú ipò àtilẹ̀wá láìsí ojúsàájú, ó sì máa ń mú sùúrù fún wọn bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.

9. (a) Ta ló ń bójú tó ọ̀ràn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá nínú ìjọ? (b) Ìgbà wo ló jẹ́ ojúṣe ẹni tá a ṣẹ̀ láti kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀ nípa ọ̀ràn náà, fún ète wo sì ni?

9 Bí ẹnì kan nínú ìjọ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, irú bíi pé ó ṣe ìṣekúṣe, kí á tètè bójú tó ọ̀ràn náà kíákíá. Ta ni kó bójú tó o? Àwọn alàgbà ni. (Jákọ́bù 5:14, 15) Àmọ́, bí ẹnì kan bá ṣẹ ẹnì kejì, bóyá nínú ọ̀ràn òwò ṣíṣe tàbí nípa ọ̀rọ̀ sísọ, nígbà náà kí ẹni tí a ṣẹ̀ kọ́kọ́ gbìyànjú láti tọ ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́ lọ ní ìdákọ́ńkọ́. (Mátíù 18:15) Bí ìyẹn ò bá yanjú ọ̀ràn náà, a jẹ́ pé ó ń béèrè ìgbésẹ̀ mìíràn síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Mátíù 18:16, 17. Nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ arákùnrin wa tó ṣẹ̀ yìí, a sì ń fẹ́ láti “jèrè” rẹ̀, ńṣe ló yẹ ká ṣe èyí lọ́nà tí ọ̀rọ̀ wa á fi lè wọ̀ ọ́ lọ́kàn.—Òwe 16:23.

10. Tí ìṣòro bá jẹ yọ, kí ni yóò jẹ́ ká lè wo ọ̀ràn náà bó ṣe tọ́?

10 Tí ìṣòro bá jẹ yọ, yálà ìṣòro ńlá tàbí ìṣòro kékeré, bí a bá gbìyànjú láti mọ irú ojú tí Jèhófà fi ń wò ó á ṣe wá láǹfààní. Kò fojúure wo ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí rárá, tó bá sì tó àkókò lójú rẹ̀, yóò mú àwọn tó ń dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá láìronúpìwàdà kúrò nínú ètò àjọ rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ká má gbàgbé pé gbogbo wa ló máa ń ṣẹ̀ láwọn ọ̀nà kéékèèké mìíràn, a sì ń fẹ́ kí Jèhófà máa fara dà á kó sì máa ṣàánú wa. Jèhófà ń tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ tó yẹ ká máa tẹ̀ lé lélẹ̀ fún wa tó bá di pé àwọn kan ṣẹ̀ wá. Tí a bá ń ṣàánú, ìfẹ́ tí Jèhófà ní là ń gbé yọ yẹn.—Éfésù 5:1, 2.

Wá Ọ̀nà Láti “Gbòòrò Síwájú”

11. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi gba àwọn ará Kọ́ríńtì níyànjú pé kí wọ́n “gbòòrò síwájú”?

11 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù ni Pọ́ọ̀lù lò lẹ́nu gbígbé ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì ní ilẹ̀ Gíríìsì ró. Ó ṣiṣẹ́ àṣekára láti ran àwọn ará tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́, ó sì fẹ́ràn wọn. Ṣùgbọ́n inú àwọn kan níbẹ̀ ò yọ́ sí i. Àríwísí ni wọ́n ń ṣe ṣáá. Ìyẹn ló fi gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n mú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń fìfẹ́ hàn “gbòòrò síwájú.” (2 Kọ́ríńtì 6:11-13; 12:15) Á dára pé kí gbogbo wa wo bí a ṣe máa ń fìfẹ́ hàn sí ọmọnìkejì wa tó, kí á sì wá ọ̀nà láti mú un gbòòrò síwájú sí i.—1 Jòhánù 3:14.

12. Báwo ni ìfẹ́ wa fún gbogbo ará inú ìjọ ṣe lè pọ̀ sí i?

12 Ǹjẹ́ àwọn kan wà nínú ìjọ tí kì í yá wa lára láti sún mọ́? Bí a bá ń sapá gidigidi láti gbójú fo àwọn ibi tí ìwà wa ti yàtọ̀ sí tiwọn, bí àwa pẹ̀lú ṣe ń fẹ́ kí àwọn náà máa ṣe sí wa, ìyẹn lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwa àti àwọn ará wọ̀nyẹn wọ̀ dáadáa. Inú wa á túbọ̀ máa dùn sí wọn bó bá jẹ́ pé àwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣe dáadáa là ń wá tí a sì ń ronú lé lórí. Dájúdájú, ìyẹn á mú kí á túbọ̀ fẹ́ràn wọn sí i.—Lúùkù 6:32, 33, 36.

13. Báwo ni a ṣe lè túbọ̀ mú ìfẹ́ wa fún àwọn ará ìjọ wa gbòòrò síwájú sí i?

13 Lóòótọ́ o, ó ní ibi tí agbára wa mọ ní ti ohun tí a lè ṣe fún àwọn èèyàn. Ó lè máà ṣeé ṣe fún wa láti máa kí gbogbo àwọn ará tán pátá nígbà ìpàdé kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí a bá se oúnjẹ tá a sì pe àwọn ọ̀rẹ́ wa wá jẹun, ó lè má ṣeé ṣe fún wa láti pe gbogbo àwọn ará pátá. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ a lè mú ìfẹ́ wa gbòòrò síwájú sí i nípa lílo ìṣẹ́jú díẹ̀ lẹ́yìn ìpàdé kọ̀ọ̀kan láti túbọ̀ mọ ẹnì kan nínú ìjọ dáadáa? Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ṣé a lè máa bá àwọn tí a ò fi bẹ́ẹ̀ sún mọ̀ jáde òde ẹ̀rí?

14. Tí a bá wà láàárín àwọn Kristẹni tí a ò tíì bá pàdé rí, báwo la ṣe lè fi ìfẹ́ tó gbóná janjan hàn sí wọn?

14 Àwọn àpéjọ àgbègbè àwa Kristẹni máa ń jẹ́ ká láǹfààní láti mú kí ìfẹ́ wa gbòòrò síwájú sí i. Ó lè tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó wà níbẹ̀. Gbogbo wọn pátá kọ́ la lè rí kí tán, ṣùgbọ́n a lè máa hùwà lọ́nà tó fi hàn pé a fi ire wọn ṣáájú ìtẹ́lọ́rùn tiwa. Lákòókò ìsinmi, a lè fi hàn pé ire wọn jẹ wá lógún nípa lílo ìdánúṣe láti kí àwọn tó wà yí wa ká. Lọ́jọ́ kan, gbogbo àwọn tó ń gbé láyé yóò di tẹ̀gbọ́n tàbúrò, tí gbogbo wọn á máa fi ìṣọ̀kan jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ àti Baba gbogbo wa. Ẹ wo bí yóò ti dùn tó láti mọ ara wa pátá nígbà yẹn! Ìfẹ́ tó gbóná janjan yóò sún wa láti fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. A ò ṣe ti ìsinsìnyí bẹ̀rẹ̀?

Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò

• Nígbà tí ìṣòro bá jẹ yọ láàárín àwọn Kristẹni, ọ̀nà wo ló yẹ ká gbà yanjú rẹ̀, kí sì nìdí rẹ̀?

• Bí a ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, àwọn ọ̀nà wo ló yẹ kí ìfẹ́ wa máa gbà pọ̀ sí i?

• Báwo ló ṣe lè ṣeé ṣe ká ní ìfẹ́ gbígbóná janjan sí àwọn èèyàn yòókù yàtọ̀ sí kìkì agbo àwọn tí a mú lọ́rẹ̀ẹ́?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 148]

A máa ń fi ìfẹ́ Kristẹni hàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà, bíi nínú àwọn ìpàdé ìjọ