Ẹni Náà Tí Gbogbo Àwọn Wòlíì Jẹ́rìí Sí
Orí Kẹrin
Ẹni Náà Tí Gbogbo Àwọn Wòlíì Jẹ́rìí Sí
1. Kí ni àwọn ohun tá a mọ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù kó tó di ẹ̀dá ènìyàn fi hàn nípa àjọṣe tó wà láàárín òun àti Jèhófà?
“BABA ní ìfẹ́ni fún Ọmọ, ó sì fi gbogbo ohun tí òun fúnra rẹ̀ ń ṣe hàn án.” (Jòhánù 5:20) Ẹ ò rí i pé àjọṣe tó lárinrin ni Ọmọ náà ní pẹ̀lú Bàbá rẹ̀, Jèhófà! Látìgbà tá a ti dá a ni àjọṣe yẹn ti bẹ̀rẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ àìmọye ọdún kó tó ṣẹ̀dá ènìyàn. Òun ni Ọmọ kan ṣoṣo tí Ọlọ́run bí, ẹnì kan ṣoṣo tí Jèhófà fọwọ́ ara rẹ̀ dá. Ọmọ àkọ́bí tó fẹ́ràn gidigidi yìí ni ó lò láti ṣẹ̀dá gbogbo nǹkan tó wà lọ́run àti lórí ilẹ̀ ayé. (Kólósè 1:15, 16) Òun náà tún ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí Agbọ̀rọ̀sọ rẹ̀, Ẹni tí Ọlọ́run ń tipasẹ̀ rẹ̀ sọ fún àwọn ènìyàn nípa ohun tí ìfẹ́ òun jẹ́. Jésù Kristi ni Ẹni yìí, òun ni Ọmọ náà tí Ọlọ́run fẹ́ràn lọ́nà àkànṣe.—Òwe 8:22-30; Jòhánù 1:14, 18; 12:49, 50.
2. Báwo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ṣe tọ́ka sí Jésù tó?
2 Ká tó lóyún Ọmọ tó jẹ́ àkọ́bí fún Ọlọ́run lọ́nà ìyanu, ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí ló ti wà lákọọ́lẹ̀ nípa rẹ̀. Àpọ́sítélì Pétérù sọ fún Kọ̀nílíù pé: “Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sí.” (Ìṣe 10:43) A tẹnu mọ́ ipa tí Jésù ń kó nínú Bíbélì tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí áńgẹ́lì kan fi sọ fún Jòhánù pé: “Jíjẹ́rìí Jésù ni ohun tí ń mí sí ìsọtẹ́lẹ̀.” (Ìṣípayá 19:10) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn fi hàn ní kedere pé òun ni Mèsáyà náà. Wọ́n jẹ́ ká mọ onírúurú ipa tó máa kó láti mú àwọn ète Ọlọ́run ṣẹ. Ó yẹ ká ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún àwọn nǹkan wọ̀nyí lónìí.
Ohun Tí Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Fi Hàn
3. (a) Nínú àsọtẹ́lẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:15, ta ni ejò náà, “obìnrin náà” àti ‘irú ọmọ ejò náà’ dúró fún? (b) Èé ṣe tí ‘pípa irú ọmọ ejò náà ní orí’ yóò fi dùn mọ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nínú?
3 Ẹ̀yìn ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì ni Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́. Jèhófà sọ fún ejò náà pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Sátánì gan-an ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ń bá wí, ẹni tí ejò náà ń ṣojú fún. Ètò àjọ olóòótọ́ ti Jèhófà ní ọ̀run, èyí tó dà bí ìyàwó fún un, sì ni “obìnrin náà.” Gbogbo àwọn áńgẹ́lì àti ẹ̀dá ènìyàn tó ní irú ẹ̀mí tí Sátánì ní, tí wọ́n sì ń ta ko Jèhófà àtàwọn èèyàn Rẹ̀, ló wà lára ‘irú ọmọ ejò’ náà. ‘Pípa ejò náà ní orí’ túmọ̀ sí ìparun tó máa dé bá ọlọ̀tẹ̀ náà Sátánì, tó ba Jèhófà lórúkọ jẹ́ tó sì fa ìbànújẹ́ ńláǹlà bá ẹ̀dá ènìyàn. Àmọ́ ta ló máa jẹ́ “irú ọmọ náà” tó máa pa ọlọ̀tẹ̀ náà run? Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni ìbéèrè yẹn fi jẹ́ “àṣírí ọlọ́wọ̀.”—Róòmù 16:20, 25, 26.
4. Báwo ni ibi tí Jésù ti ṣẹ̀ wá ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé òun ni Irú Ọmọ náà tá a ṣèlérí?
4 Jèhófà pèsè àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ sí i lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún méjì ọdún nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Ó sọ pé látinú ìlà ìdílé Ábúráhámù ni Irú Ọmọ náà á ti wá. (Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18) Àmọ́ ṣá, kì í ṣe pé ìlà ìdílé kan á kàn mú Irú Ọmọ náà jáde ṣá, bí kò ṣe pé èyí tí Ọlọ́run bá yàn ló máa ṣe bẹ́ẹ̀. Bí Ábúráhámù ṣe fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ Íṣímáẹ́lì, tí Hágárì bí fún un tó, Jèhófà sọ pé: “Májẹ̀mú mi ni èmi yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú Ísákì, ẹni tí Sárà yóò bí fún ọ.” (Jẹ́nẹ́sísì 17:18-21) Nígbà tó yá, májẹ̀mú náà ṣẹ, àmọ́ kò ṣẹ sí Ísọ̀ tó jẹ́ àkọ́bí Ísáákì lára o, Jákọ́bù ló ṣẹ sí lára, ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ni ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì ti ṣẹ̀ wá. (Jẹ́nẹ́sísì 28:10-14) Nígbà tó ṣe, a sọ pé inú ẹ̀yà Júdà, nínú ìlà ìdílé Dáfídì la ó ti bí Irú Ọmọ náà.—Jẹ́nẹ́sísì 49:10; 1 Kíróníkà 17:3, 4, 11-14.
5. Kí ló fi ẹ̀rí hàn pé Jésù ni Mèsáyà náà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?
5 Àwọn nǹkan mìíràn wo la tún sọ nípa bí a ó ṣe dá Irú Ọmọ náà mọ̀? Ó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọdún ṣáájú tí Bíbélì ti sọ pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù lá ti máa bí Irú Ọmọ tá a ṣèlérí náà. Ó tún fi yéni pé Irú Ọmọ náà tiẹ̀ ti wà láti “àwọn ọjọ́ tí ó jẹ́ àkókò tí ó lọ kánrin,” látìgbà tá a ti dá a ní ọ̀run. (Míkà 5:2) A tún gba ẹnu wòlíì Dáníẹ́lì sàsọtẹ́lẹ̀ nípa àkókò náà gan-an tó máa fara hàn bíi Mèsáyà lórí ilẹ̀ ayé. (Dáníẹ́lì 9:24-26) Nígbà tá a sì fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jésù, tó tipa bẹ́ẹ̀ di Ẹni Àmì Òróró Jèhófà, ohùn Ọlọ́run tó dún láti ọ̀run fi hàn pé Ọmọ Rẹ̀ ni lóòótọ́. (Mátíù 3:16, 17) Bá a ṣe fi Irú Ọmọ náà hàn nìyẹn o! Èyí ló jẹ́ kí Fílípì lè fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ pé: “Àwa ti rí ẹni tí Mósè, nínú Òfin, àti àwọn Wòlíì kọ̀wé nípa rẹ̀, Jésù.”—Jòhánù 1:45.
6. (a) Gẹ́gẹ́ bí Lúùkù 24:27 ti wí, kí làwọn ọmọlẹ́yìn wá lóye rẹ̀? (b) Ta ni ‘irú ọmọ obìnrin náà’ gan-an, kí sì ni fífọ́ tó máa fọ́ orí ejò náà túmọ̀ sí?
6 Nígbà tó yá, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù wá rí i pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ ló wà nínú Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí. (Lúùkù 24:27) Ó wá túbọ̀ ṣe kedere pé Jésù gan-an ni ‘irú ọmọ obìnrin náà,’ ẹni tó máa fọ́ orí ejò náà, tí yóò sì mú Sátánì kúrò pátápátá. Nípasẹ̀ Jésù ni gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run ti sọ pé òun á ṣe fún ìran ènìyàn àti gbogbo nǹkan tá a ti ń hára gàgà láti rí, máa di ṣíṣe.—2 Kọ́ríńtì 1:20.
7. Tá a bá ti mọ Ẹni náà táwọn àsọtẹ́lẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, kí ló tún yẹ ká mọ̀?
7 Kí ló yẹ kí ohun tá a mọ̀ yìí sún wa ṣe? Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìwẹ̀fà ará Etiópíà kan tó ti ka àwọn kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí nípa Olùràpadà àti Mèsáyà tó ń bọ̀. Ọ̀rọ̀ náà rú u lójú, ó béèrè lọ́wọ́ Fílípì ajíhìnrere pé: “Ta ni wòlíì náà sọ èyí nípa rẹ̀?” Ìwẹ̀fà náà kò mà sọ pé ọ̀rọ̀ ti bùṣe nígbà tó rí ìdáhùn gbà o. Ìgbà tó tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí àlàyé tí Fílípì ṣe, lọkùnrin náà wá rí i pé ó yẹ kóun ṣe nǹkan kan láti fi hàn pé òun mọrírì àsọtẹ́lẹ̀ tó ní ìmúṣẹ yìí. Ó rí i pé òun gbọ́dọ̀ ṣe ìrìbọmi. (Ìṣe 8:32-38; Aísáyà 53:3-9) Ǹjẹ́ àwa náà ń ṣe bẹ́ẹ̀?
8. (a) Kí ni fífi tí Ábúráhámù fẹ́ fi Ísáákì rúbọ ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ fún Ábúráhámù pé nípa Irú Ọmọ náà ni gbogbo orílẹ̀-èdè ti máa bù kún ara wọn, báwo sì lèyí ṣe kàn wá lónìí?
8 Tún wo ti ìtàn tó ń mára ẹni bù máṣọ, ìyẹn ti Ábúráhámù tó fẹ́ fi ọmọ kan ṣoṣo tí Sárà bí fún un rúbọ. (Jẹ́nẹ́sísì 22:1-18) Èyí ṣàpẹẹrẹ ohun tí Jèhófà ṣe, ìyẹn bó ṣe fi Ọmọ kan ṣoṣo tó ní rúbọ: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Èyí mú un dá wa lójú pé bí Jèhófà ṣe fún wa ní Ọmọ kan ṣoṣo tó bí láti mú ète Rẹ̀ ṣẹ, bákan náà ni Ó ṣe máa “fi inú rere fún wa ní gbogbo ohun yòókù pẹ̀lú rẹ̀.” (Róòmù 8:32) Kí wá ló yẹ ká ṣe? Gẹ́gẹ́ bá a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì 22:18, Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé gbogbo orílẹ̀-èdè ló máa bù kún ara wọn nípasẹ̀ Irú Ọmọ náà, “nítorí òtítọ́ náà pé [Ábúráhámù] ti fetí sí ohùn [Ọlọ́run].” Ó yẹ kí àwa náà fetí sí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kì yóò rí ìyè, ṣùgbọ́n ìrunú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.”—Jòhánù 3:36.
9. Kí lohun tá a máa ṣe tá a bá mọrírì ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tí ẹbọ Jésù mú kó ṣeé ṣe?
Mátíù 22:37-39) Jésù sọ pé ìfẹ́ wa fún Jèhófà á sún wa láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn kí wọ́n lè “máa pa gbogbo ohun tí [Jésù] ti pa láṣẹ fún [wa] mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) A tún gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ yẹn hàn sí àwọn tá a jọ jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà nípa bíbá wọn ‘pé jọ pọ̀’ déédéé. (Hébérù 10:25; Gálátíà 6:10) Kò tán síbẹ̀ o, bá a ṣe ń tẹ́tí sí Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ ronú pé ohun tí wọ́n ń béèrè ni pé ká má ṣe àṣìṣe. Hébérù 4:15 sọ pé Jésù, tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà wa lè “báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa.” Ìtùnú ńlá gbáà mà lèyí o, pàápàá nígbà tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi pe kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tá a ní.—Mátíù 6:12.
9 Bá a bá mọrírì ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tí ẹbọ Jésù mú kó ṣeé ṣe, a kò ní lọ́ra láti ṣe àwọn ohun tí Jèhófà ti gba ẹnu Jésù sọ fún wa. Èyí kan ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wa. (Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Kristi
10. Èé ṣe tí kò fi sí ìgbàlà níbòmíràn àyàfi lọ́dọ̀ Jésù Kristi?
10 Lẹ́yìn tí Àpọ́sítélì Pétérù ti ṣàlàyé fún wọn ní ilé ẹjọ́ gíga tó wà ní Jerúsálẹ́mù pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti ṣẹ sí Jésù lára, ó wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó rinlẹ̀ pé: “Kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn, nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run tí a ti fi fúnni láàárín àwọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a ó fi gbà wá là.” (Ìṣe 4:12) Ìgbà tó kúkú jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù, ikú wọn kò lè ra ẹnikẹ́ni padà. Àmọ́ ẹni pípé ni Jésù, ìwàláàyè rẹ̀ sì ní ìtóye ẹbọ. (Sáàmù 49:6-9; Hébérù 2:9) Ẹbọ ìràpadà tó rú sí Ọlọ́run jẹ́ ọgbọọgba pẹ̀lú ìwàláàyè pípé tí Ádámù pàdánù. (1 Tímótì 2:5, 6) Èyí ló fún wa láǹfààní láti ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun Ọlọ́run.
11. Ṣàlàyé bí ẹbọ Jésù ṣe lè ṣe wá láǹfààní tó.
11 Ìràpadà náà tún fún wa láyè láti gbádùn àwọn àǹfààní mìíràn lákòókò tá a wà yìí pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, ẹbọ Jésù mú ká lè ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ nítorí pé à ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ni eléyìí fi dára ju ti ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń fi ẹran rúbọ níbàámu pẹ̀lú ohun tí Òfin Mósè ní kí wọ́n ṣe. (Ìṣe 13:38, 39; Hébérù 9:13, 14; 10:22.) Àmọ́ o, rírí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà lọ́nà yìí béèrè pé ká fi tinútinú gbà pé lóòótọ́ la nílò ẹbọ Kristi: “Bí a bá sọ gbólóhùn náà pé: ‘Àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan,’ a ń ṣi ara wa lọ́nà ni, òtítọ́ kò sì sí nínú wa. Bí a bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, òun jẹ́ aṣeégbíyèlé àti olódodo tí yóò fi dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, tí yóò sì wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo àìṣòdodo.”—1 Jòhánù 1:8, 9.
12. Èé ṣe tí ṣíṣe ìrìbọmi fi ṣe pàtàkì láti ní ẹ̀rí ọkàn rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
12 Báwo làwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe lè ní ìgbàgbọ́ nínú Kristi àti ẹbọ rẹ̀? Nígbà táwọn èèyàn ọ̀rúndún kìíní di onígbàgbọ́, wọ́n fi èyí hàn níṣojú ọ̀pọ̀ èèyàn. Báwo? Wọ́n ṣe ìrìbọmi. Èé ṣe? Nítorí Jésù pàṣẹ pé kí gbogbo ọmọlẹ́yìn òun ṣe ìrìbọmi. (Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 8:12; 18:8) Bí ẹ̀bùn onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà tipasẹ̀ Jésù pèsè yìí bá wú ẹnì kan lórí lóòótọ́, onítọ̀hún kò ní lọ́ra láti ṣe ohun tó tọ́. Ẹni bẹ́ẹ̀ á ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, á ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run nínú àdúrà, á sì fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Fífi ìgbàgbọ́ hàn lọ́nà yìí ló fi hàn pé ẹni náà ń ‘béèrè ẹ̀rí ọkàn rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.’—1 Pétérù 3:21.
13. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí i pé a ti dẹ́ṣẹ̀, èé sì ti ṣe?
1 Jòhánù 2:1, 2) Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé irú ẹ̀ṣẹ̀ yòówù ká dá, bá a bá ti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run dárí jì wá àbùṣe bùṣe nìyẹn? Bẹ́ẹ̀ kọ́ o. Ojúlówó ìrònúpìwàdà ló lè mú kéèyàn rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà o. A lè nílò ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà, tí wọ́n nírìírí jù wá lọ nínú ìjọ Kristẹni. A gbọ́dọ̀ gbà pé ohun tá a ṣe kù díẹ̀ káà tó ká sì mọ ìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀, ká fi hàn pé ó dùn wá dọ́kàn ká sì sapá láti má ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. (Ìṣe 3:19; Jákọ́bù 5:13-16) Tá a bá ṣe èyí, ó dájú pé Jésù yóò ràn wá lọ́wọ́ àá sì tún padà rí ojú rere Jèhófà.
13 Àmọ́ ká sòótọ́, lẹ́yìn téèyàn ti ṣèrìbọmi, ó ṣì lè dẹ́ṣẹ̀. Kí ló lè ṣe tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀? Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Mo ń kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín kí ẹ má bàa dá ẹ̀ṣẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, bí ẹnikẹ́ni bá dá ẹ̀ṣẹ̀, àwa ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe olódodo. Òun sì ni ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (14. (a) Sọ ọ̀nà pàtàkì kan tí ẹbọ Jésù gbà ṣe wá láǹfààní. (b) Tá a bá ní ìgbàgbọ́ lóòótọ́, kí la máa ṣe?
14 Ẹbọ Jésù ló fún àwọn “agbo kékeré” náà láǹfààní ìyè ayérayé ní òkè ọ̀run, ìyẹn àwọn apá kejì irú ọmọ náà tí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 sọ. (Lúùkù 12:32; Gálátíà 3:26-29) Bákan náà ló tún fún ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù èèyàn ní àǹfààní ìyè ayérayé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:29; Ìṣípayá 20:11, 12; 21:3, 4) Ìyè àìnípẹ̀kun ni “ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni . . . nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23; Éfésù 2:8-10) Bá a bá ní ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀bùn yẹn tá a sì mọrírì ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà mú kó ṣeé ṣe, ó máa hàn nínú ìṣe wa. Bá a bá fi òye mọ ọ̀nà àgbàyanu tí Jèhófà gbà lo Jésù láti ṣàṣeparí ohun tí Ó fẹ́ kí Jésù ṣe, àti bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kí gbogbo wa tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí, iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni yóò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbòkègbodò tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wa. Bá a ṣe ń fi ìdánilójú sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ẹ̀bùn gíga lọ́lá yìí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló máa fi hàn pé àwa náà ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.—Ìṣe 20:24.
15. Báwo ni ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi ṣe ń mú ìṣọ̀kan wá?
15 Ẹ ò rí i pé irú ìgbàgbọ́ yìí dára gan-an ni, ó sì ń mú ìṣọ̀kan wá! Òun ló ń mú ká lè sún mọ́ Jèhófà, ká lè sún mọ́ Ọmọ rẹ̀, ká sì lè sún mọ́ àwọn ará wa nínú ìjọ Kristẹni. (1 Jòhánù 3:23, 24) Ó ń mú inú wa dùn pé Jèhófà ti finú rere fún Ọmọ rẹ̀ ní “orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn [yàtọ̀ sí orúkọ Ọlọ́run], kí ó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba ti àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀, kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run Baba.”—Fílípì 2:9-11.
Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò
• Nígbà tí Mèsáyà náà fara hàn, èé ṣe tí irú ẹni tó jẹ́ fi hàn kedere sí àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lóòótọ́?
• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tó yẹ ká ṣe láti fi hàn pé a mọrírì ẹbọ Jésù?
• Àwọn ọ̀nà wo ni ẹbọ Jésù gbà ṣe wá láǹfààní? Báwo lèyí ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ń gbàdúrà pé kí Jèhófà dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 36]
Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti máa pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́