Báwo Ni Jèhófà Ṣe Ń Darí Ètò Rẹ̀?
Orí Kẹrìnlá
Báwo Ni Jèhófà Ṣe Ń Darí Ètò Rẹ̀?
1. Ìsọfúnni wo ni Bíbélì fún wa nípa ètò Jèhófà, èé sì ti ṣe tó fi ṣe pàtàkì fún wa?
ǸJẸ́ Ọlọ́run ní ètò kan? Ìwé Mímọ́ tá a mí sí sọ pé ó ní. Nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó jẹ́ ká kófìrí ètò rẹ̀ àgbàyanu ní ọ̀run. (Ìsíkíẹ́lì 1:1, 4-14; Dáníẹ́lì 7:9, 10, 13, 14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè rí apá tí kò ṣeé fojú rí yìí, ó ń kó ipa pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́ lóde òní. (2 Àwọn Ọba 6:15-17) Ètò Jèhófà tún ní apá kan tó ṣeé fojú rí, lórí ilẹ̀ ayé. Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó jẹ́ àti bí Jèhófà ṣe ń darí rẹ̀.
Dídá Apá Tó Ṣeé Fojú Rí Mọ̀
2. Ìjọ tuntun wo ni Ọlọ́run dá sílẹ̀?
2 Fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ ọdún ó lé márùndínláàádọ́ta [1,545] ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fi jẹ́ ìjọ Ọlọ́run. (Ìṣe 7:38) Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì kò pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Ó tiẹ̀ kọ Ọmọ rẹ̀ pàápàá sílẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi kọ ìjọ yẹn sílẹ̀, tí ó sì pa á tì. Jésù sọ fáwọn Júù pé: “Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.” (Mátíù 23:38) Ọlọ́run wá dá ìjọ tuntun sílẹ̀, èyí tó bá dá májẹ̀mú tuntun. Ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ni àpapọ̀ iye ọmọ ìjọ yìí. Ọlọ́run ló yàn wọ́n láti wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ ní ọ̀run.—Ìṣípayá 14:1-4.
3. Kí ló wáyé nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa tó fi hàn kedere pé ìjọ tuntun kan ni Ọlọ́run ń lò báyìí?
3 Ìgbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa ni JèhófÌṣe 2:1-4) Báyìí ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe fi hàn kedere pé èyí ni àwùjọ àwọn èèyàn tí Ọlọ́run ń lò nísinsìnyí láti mú ète rẹ̀ ṣẹ lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi lókè ọ̀run.
à fi ẹ̀mí rẹ̀ yan àwọn tó kọ́kọ́ wà lára ìjọ tuntun yẹn. A kà nípa ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé yẹn pé: “Wàyí o, bí ọjọ́ àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ti ń lọ lọ́wọ́, gbogbo wọ́n wà pa pọ̀ ní ibì kan náà, lójijì, ariwo kan dún láti ọ̀run gan-an gẹ́gẹ́ bíi ti atẹ́gùn líle tí ń rọ́ yìì, ó sì kún inú gbogbo ilé tí wọ́n jókòó sí. Àwọn ahọ́n bí ti iná sì di rírí fún wọn, ó sì pín káàkiri, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì bà lé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, gbogbo wọ́n sì wá kún fún ẹ̀mí mímọ́.” (4. Àwọn wo ló para pọ̀ jẹ́ ètò Jèhófà tó ṣeé fojú rí lónìí?
4 Lónìí, kìkì àṣẹ́kù kéréje lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yẹn ló wà láyé. Àmọ́, ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ọ̀kẹ́ àìmọye “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn,” ló ti dara pọ̀ mọ́ àṣẹ́kù ẹni àmì òróró. Jésù, Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà, ti so àwọn àgùntàn mìíràn wọ̀nyí pọ̀ ṣọ̀kan mọ́ àṣẹ́kù náà, wọ́n sì wá di agbo kan ṣoṣo lábẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùṣọ́ Àgùntàn kan ṣoṣo fún agbo náà. (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:11, 16) Gbogbo wọn wá jẹ́ ìjọ kan ṣoṣo tó wà níṣọ̀kan, ìyẹn ètò Jèhófà tó ṣeé fojú rí.
Ètò Tí Ọlọ́run Ń Darí
5. Ta ló ń darí ètò Ọlọ́run, báwo ló sì ṣe ń darí rẹ̀?
5 Gbólóhùn náà, “ìjọ Ọlọ́run alààyè,” tá a rí nínú Ìwé Mímọ́, fi ẹni tí ń darí rẹ̀ hàn kedere. Ọlọ́run ló ń ṣàkóso ètò náà. Jèhófà ń darí àwọn èèyàn rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù, ẹni tí Òun fi jẹ Orí tí kò ṣeé fojú rí fún ìjọ. Ó tún ń darí àwọn èèyàn rẹ̀ nípasẹ̀ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ tí Òun 1 Tímótì 3:14, 15; Éfésù 1:22, 23; 2 Tímótì 3:16, 17.
fúnra rẹ̀ mí sí.—6. (a) Báwo ló ṣe hàn gbangba ní ọ̀rúndún kìíní pé látọ̀runwá la ti ń darí ìjọ? (b) Kí ló fi hàn pé Jésù ṣì ni Orí ìjọ?
6 Ìdarí yẹn hàn gbangba nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì. (Ìṣe 2:14-18, 32, 33) Ó ṣe kedere nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà darí títan ìhìn rere náà dé Áfíríkà, àti nígbà tí Jésù fáwọn èèyàn nítọ̀ọ́ni lákòókò tá a yí Sọ́ọ̀lù ará Tásù lọ́kàn padà, àti nígbà tí Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí wàásù láàárín àwọn Kèfèrí. (Ìṣe 8:26, 27; 9:3-7; 10:9-16, 19-22) Àmọ́ o, nígbà tó yá, a ò gbóhùn látọ̀run mọ́, a ò rí áńgẹ́lì mọ́, a ò fúnni ní ẹ̀bùn ẹ̀mí lọ́nà iṣẹ́ ìyanu mọ́. Ṣùgbọ́n Jésù ṣèlérí pé: “Wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 28:20; 1 Kọ́ríńtì 13:8) Lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé Jésù ló ń darí ìjọ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, kò ní ṣeé ṣe láti máa pòkìkí ìhìn Ìjọba náà lójú àtakò gbígbóná janjan.
7. (a) Àwọn wo ló para pọ̀ jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” èé sì ti ṣe? (b) Iṣẹ́ wo la gbé lé “ẹrú” náà lọ́wọ́?
7 Kété ṣáájú ikú Jésù, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tí òun Ọ̀gá máa gbé àkànṣe ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́. “Ẹrú” yẹn yóò wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà tí Olúwa bá gòkè re ọ̀run, yóò sì máa báṣẹ́ lọ pẹrẹu nígbà tí Kristi bá padà wá láìṣeé fojú rí nínú agbára Ìjọba náà. Ó dájú pé àpèjúwe yẹn kò lè tọ́ka sí èèyàn kan ṣoṣo gíro. Ṣùgbọ́n àpèjúwe yẹn bá ìjọ ẹni àmì òróró Kristi mu. Jésù pè é ní “ẹrú” òun nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ ló fi rà á. Ó pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ “ẹrú” yẹn máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, Mátíù 24:45-47; 28:19; Aísáyà 43:10; Lúùkù 12:42; 1 Pétérù 4:10.
kí wọ́n máa bọ́ wọn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, kí wọ́n sì máa fún wọn ní “oúnjẹ [tẹ̀mí] wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.”—8. (a) Àwọn ẹrù iṣẹ́ wo ni ẹgbẹ́ ẹrú náà ní báyìí? (b) Kí nìdí tí ojú tá a fi ń wo ìtọ́ni tó ń jáde nípasẹ̀ ọ̀nà tí Ọlọ́run ń lò fi ṣe pàtàkì?
8 Níwọ̀n bí ẹgbẹ́ ẹrú yìí ti ń fi ìṣòtítọ́ ṣe iṣẹ́ Ọ̀gá rẹ̀ nígbà tó padà dé láìṣeé fojú rí lọ́dún 1914, ẹ̀rí wà pé a fi kún ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ lọ́dún 1919. Láti ọdún yẹn wá la ti túbọ̀ jára mọ́ iṣẹ́ ìjẹ́rìí kárí ayé nípa Ìjọba náà, a sì ń kó ogunlọ́gọ̀ ńlá tó jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà jọ kí wọ́n lè la ìpọ́njú ńlá já. (Mátíù 24:14, 21, 22; Ìṣípayá 7:9, 10) Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú nílò oúnjẹ tẹ̀mí. Ẹgbẹ́ ẹrú náà sì ń pèsè rẹ̀ fún wọn. Fún ìdí yìí, bí a óò bá múnú Jèhófà dùn, a ní láti máa gba ìtọ́ni tí ó ń pèsè nípasẹ̀ ọ̀nà yìí, ká sì máa tẹ̀ lé e.
9, 10. (a) Ní ọ̀rúndún kìíní, ìṣètò wo ló wà fún yíyanjú àwọn ìbéèrè nípa ẹ̀kọ́ àti nípa dídarí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà? (b) Ìṣètò wo ló wà lóde òní fún dídarí iṣẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà?
9 Nígbà mìíràn, àwọn ìbéèrè máa ń dìde lórí ẹ̀kọ́ àti ọ̀nà ìgbà-ṣe-nǹkan. Kí wá ni ṣíṣe? Ìwé Ìṣe orí kẹẹ̀ẹ́dógún sọ fún wa nípa bí wọ́n ṣe yanjú ọ̀ràn kan tó dìde nípa àwọn Kèfèrí tó di onígbàgbọ́. Wọ́n gbé ọ̀ràn náà lọ síwájú àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbààgbà ní Jerúsálẹ́mù, ìyẹn àwọn tó dúró gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ olùṣàkóso àpapọ̀. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn kì í ṣe ẹni tí kò lè ṣàṣìṣe, ṣùgbọ́n Ọlọ́run lò wọ́n. Wọ́n gbé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí ọ̀ràn náà yẹ̀ wò. Wọ́n tún gbé ẹ̀rí tó wà nílẹ̀ yẹ̀ wò nípa bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe lọ́wọ́ sí bíbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù láàárín àwọn Kèfèrí. Wọ́n wá ṣe ìpinnu. Ọlọ́run bù kún ìṣètò yẹn. (Ìṣe 15:1-29; 16:4, 5) Ẹgbẹ́ olùṣàkóso yẹn tún rán àwọn èèyàn jáde láti mú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà tẹ̀ síwájú.
10 Lóde òní, àwọn arákùnrin tá a fẹ̀mí yàn láti onírúurú ilẹ̀ ló para pọ̀ jẹ́ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ètò Jèhófà tó ṣeé fojú rí. Gbogbo wọ́n wà ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbàáyé. Lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ń gbé ìjọsìn mímọ́ lárugẹ ní gbogbo ilẹ̀, wọ́n sì ń darí iṣẹ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rùn-ún ìjọ wọn. Ojú ìwòye Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso kò yàtọ̀ sí ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó kọ̀wé sáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Kì í ṣe pé a jẹ́ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ yín, ṣùgbọ́n a jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú yín, nítorí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín ni ẹ dúró.”—2 Kọ́ríńtì 1:24.
11. (a) Báwo la ṣe ń yan àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tá a yàn sípò?
11 Ojú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé ń wò fún yíyan àwọn arákùnrin tó tóótun, tí àwọn náà ẹ̀wẹ̀, sì láṣẹ láti yan àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti máa bójú tó ìjọ. Àwọn ohun tí ẹni tí a ó yàn gbọ́dọ̀ dójú ìlà rẹ̀ wà nínú Bíbélì, ó sì yẹ láti fi sọ́kàn pé ẹ̀dá aláìpé tó lè ṣàṣìṣe làwọn ọkùnrin yìí. Àwọn alàgbà tó ń dámọ̀ràn ẹni, àtàwọn tó ń yanni sípò ní ẹrù iṣẹ́ wíwúwo níwájú Ọlọ́run. (1 Tímótì 3:1-10, 12, 13; Títù 1:5-9) Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń gbàdúrà pé kí ẹ̀mí Ọlọ́run ran àwọn lọ́wọ́, tí wọ́n sì ń wá ìtọ́sọ́nà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí. (Ìṣe 6:2-4, 6; 14:23) Ẹ jẹ́ ká máa fi hàn pé a mọyì “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” wọ̀nyí, tí wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ láti dé “ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́.”—Éfésù 4:8, 11-16.
12. Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo àwọn obìnrin nínú ìṣètò ìṣàkóso Ọlọ́run?
12 Ìwé Mímọ́ lànà pé àwọn ọkùnrin ni kó máa bójú tó ìjọ. Èyí kò rẹ àwọn obìnrin sílẹ̀, nítorí pé àwọn kan lára wọ́n jẹ́ ajogún Ìjọba ọ̀run, wọ́n sì ń ṣe gudugudu méje nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. (Sáàmù 68:11) Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn obìnrin ń gbé orúkọ rere ìjọ ga nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe ojúṣe wọn nínú ìdílé nígbà gbogbo. (Títù 2:3-5) Àmọ́ àwọn ọkùnrin tá a yàn sípò ló ni iṣẹ́ kíkọ́ni nínú ìjọ.—1 Tímótì 2:12, 13.
13. (a) Ojú wo ni Bíbélì rọ àwọn alàgbà pé kí wọ́n máa fi wo ipò wọn? (b) Àǹfààní wo ni gbogbo wa ní?
13 Nínú ayé, ojú èèyàn pàtàkì ni wọ́n fi ń wo ẹni tó bá wà ní ipò gíga. Ṣùgbọ́n nínú ètò Ọlọ́run, ìlànà tá à ń tẹ̀ lé ni: “Ẹni tí ó bá hùwà bí ẹni tí ó kéré jù láàárín gbogbo yín ni ẹni ńlá.” (Lúùkù 9:46-48; 22:24-26) Ìwé Mímọ́ fún àwọn alàgbà nímọ̀ràn pé kí wọ́n yẹra fún jíjẹ gàba lórí àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo. (1 Pétérù 5:2, 3) Kì í ṣe kìkì àwọn kéréje tá a yàn, bí kò ṣe gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ló ní àǹfààní ṣíṣojú fún Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, bí wọ́n ti ń fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ̀, tí wọ́n sì ń sọ nípa Ìjọba rẹ̀ fáwọn èèyàn níbi gbogbo.
14. Fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí jíròrò àwọn ìbéèrè tó wà ní ìparí ìpínrọ̀ yìí.
14 Á dáa ká bi ara wa pé: ‘Ṣé lóòótọ́ ni mo mọrírì bí Jèhófà ṣe ń darí ètò rẹ̀ tó ṣeé fojú rí? Ṣé ìṣesí mi àti ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti ìwà mi ń fi ìmọrírì yẹn hàn?’ Ríronú lórí àwọn kókó tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí lè ran kálukú wa lọ́wọ́ láti fojú ṣùnnùkùn wo ọ̀ràn náà.
Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni mo gbà pé Kristi ni Orí ìjọ, nígbà náà, gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí ṣe fi hàn, kí ló yẹ kí n máa ṣe? (Mátíù 24:14; 28:19, 20; Jòhánù 13:34, 35)
Bí mo bá fi ìmọrírì tẹ́wọ́ gba àwọn ìpèsè tẹ̀mí tó Lúùkù 10:16)
ń wá látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ẹrú náà àti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso rẹ̀, ta ni mò ń bọ̀wọ̀ fún? (Báwo ló ṣe yẹ kí kálukú nínú ìjọ, àgàgà àwọn alàgbà, máa ṣe síra wọn? (Róòmù 12:10)
15. (a) Kí ni ìṣarasíhùwà wa sí ètò Jèhófà tó ṣeé fojú rí ń fi hàn? (b) Àwọn àǹfààní wo la ní láti fi Èṣù hàn ní òpùrọ́, ká sì mú Jèhófà lọ́kàn yọ̀?
15 Jèhófà ń tọ́ wa sọ́nà lónìí nípasẹ̀ ètò rẹ̀ tó ṣeé fojú rí lábẹ́ ìdarí Kristi. Ìṣarasíhùwà wa sí ìṣètò yìí yóò fi ìhà tá a wà nínú ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ hàn. (Hébérù 13:17) Ohun tí Sátánì ń sọ ni pé ọ̀ràn ara wa ló ká wa lára jù. Àmọ́ tá a bá ń sìn ní ibikíbi tí wọ́n bá fi wá sí, tá a sì yẹra fún ìwà ṣekárími, à ń fi hàn pé òpùrọ́ ni Èṣù. Bá a bá fẹ́ràn àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín wa, tá a sì ń bọ̀wọ̀ fún wọn, àmọ́ tá à ń yàgò fún ‘kíkan sáárá sí àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn nítorí àǹfààní tara wa,’ a óò múnú Jèhófà dùn. (Júúdà 16; Hébérù 13:7) Nípa dídúró ṣinṣin ti ètò Jèhófà, à ń fi hàn pé Jèhófà ni Ọlọ́run wa àti pé à ń fi ìṣọ̀kan sìn ín.—1 Kọ́ríńtì 15:58.
Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò
• Kí ni ètò Jèhófà tó ṣeé fojú rí lóde òní? Kí ni ète rẹ̀?
• Ta ni a yàn gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ, àwọn ètò tó ṣeé fojú rí wo ló sì ṣe láti fún wa ní ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́?
• Ẹ̀mí rere wo ló yẹ ká ní sáwọn tó wà nínú ètò Jèhófà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 133]
Jèhófà ń tọ́ wa sọ́nà nípasẹ̀ ètò rẹ̀ tó ṣeé fojú rí lábẹ́ ìdarí Kristi