Fetí sí Ìmọ̀ràn, Gba Ìbáwí
Orí Kẹẹ̀ẹ́dógún
Fetí sí Ìmọ̀ràn, Gba Ìbáwí
1. (a) Kí nìdí tí gbogbo wa fi nílò ìmọ̀ràn àti ìbáwí? (b) Ìbéèrè wo ló yẹ ká ronú lé lórí?
JÁKỌ́BÙ 3:2 sọ pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” Ó ṣeé ṣe ká rántí ọ̀pọ̀ ìgbà tí a ti kùnà láti jẹ́ irú ẹni tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká jẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, a gbà pé òdodo ọ̀rọ̀ ni Bíbélì sọ, nígbà tó sọ pé: “Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ìbáwí, kí o lè di ọlọ́gbọ́n ní ọjọ́ ọ̀la rẹ.” (Òwe 19:20) Ó dájú pé a ti ṣe àwọn àtúnṣe nínú ìgbésí ayé wa láti lè máa fi ohun tí Bíbélì kọ́ wa ṣèwà hù. Ṣùgbọ́n kí ló máa ń jẹ́ ìṣarasíhùwà wa bí Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa bá fún wa nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn kan?
2. Kí ló yẹ ká ṣe nígbà tẹ́nì kan bá fún wa nímọ̀ràn?
2 Ohun tí àwọn kan máa ń ṣe ni pé wọ́n á máa wá àwáwí, wọ́n á ní ọ̀rọ̀ yẹn ò tó bí onítọ̀hún ṣe ń wò ó, tàbí kí wọ́n ti ẹ̀bi ọ̀rọ̀ yẹn sórí àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n ohun tó ti dáa ni pé ká máa fetí sí ìmọ̀ràn kí á sì ṣiṣẹ́ lé e lórí. (Hébérù 12:11) Lóòótọ́, kò yẹ kí ẹnikẹ́ni máa retí pé káwọn èèyàn máa ṣe nǹkan lọ́nà pípé, tàbí pé kó máa fúnni nímọ̀ràn ṣáá lórí àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tàbí lórí àwọn nǹkan tí Bíbélì fi sílẹ̀ pé kí kálukú ṣe ohun tó bá wù ú. Bákan náà, ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé ẹni tó ń fúnni nímọ̀ràn ò tíì gbé gbogbo ọ̀ràn náà yẹ̀ wò délẹ̀, a sì lè jẹ́ kó mọ̀ bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àmọ́ nínú àwọn àlàyé tí a fẹ́ ṣe yìí, ẹ jẹ́ ká gbà pé ìmọ̀ràn tàbí ìbáwí tí à ń wí yìí jẹ́ èyí tó yẹ, tó sì bá Bíbélì mu. Ìhà wo ló yẹ ká kọ sí i?
Àwọn Àpẹẹrẹ Tó Yẹ Ká Fi Kọ́gbọ́n
3, 4. (a) Kí ló wà nínú Bíbélì tó lè mú ká máa fi ojú tó tọ́ wo ìmọ̀ràn àti ìbáwí? (b) Ìhà wo ni Sọ́ọ̀lù Ọba kọ sí ìmọ̀ràn, kí sì ni àbáyọrí rẹ̀?
3 Ìtàn àwọn èèyàn tí a fún nímọ̀ràn yíyẹ pọ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbà mìíràn ó máa ń jẹ́ ìmọ̀ràn tòun ti ìbáwí. Sọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì jẹ́ ọ̀kan lára irú àwọn èèyàn yẹn. Kò ṣègbọràn sí Jèhófà ní ti ọ̀ràn orílẹ̀-èdè Ámálékì. Àwọn ará Ámálékì dojúùjà kọ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, ni Jèhófà bá ṣèdájọ́ pé kó má ṣe dá èyíkéyìí nínú àwọn ará Ámálékì tàbí agbo ẹran ọ̀sìn wọn sí. Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù Ọba dá ọba wọn àti àwọn tó dára jù lọ nínú ẹran ọ̀sìn wọn sí.—1 Sámúẹ́lì 15:1-11.
4 Ni Jèhófà bá rán Sámúẹ́lì wòlíì pé kí ó lọ bá Sọ́ọ̀lù wí. Kí ni Sọ́ọ̀lù wá ṣe? Ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ àròyé pé ṣebí òun sáà ti ṣẹ́gun àwọn ará Ámálékì, pé ọba wọn nìkan lòun kàn dá sí. Bẹ́ẹ̀ kẹ́, ìyẹn lòdì sí àṣẹ tí Jèhófà fún un o. (1 Sámúẹ́lì 15:20) Sọ́ọ̀lù wá gbìyànjú láti ti ẹ̀bi dídá tó dá àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sí sórí àwọn èèyàn rẹ̀, ó ní: “Mo bẹ̀rù àwọn ènìyàn náà . . . mo sì ṣègbọràn sí ohùn wọn.” (1 Sámúẹ́lì 15:24) Ó jọ pé bó ṣe máa gbayì ló jẹ ẹ́ lógún, ó tiẹ̀ ní kí Sámúẹ́lì bọlá fún òun níwájú àwọn èèyàn pàápàá. (1 Sámúẹ́lì 15:30) Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Jèhófà kọ Sọ́ọ̀lù lọ́ba.—1 Sámúẹ́lì 16:1.
5. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ùsáyà Ọba nígbà tó kọ ìmọ̀ràn?
5 Ùsáyà ọba Júdà “ṣe àìṣòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, tí ó sì wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí.” (2 Kíróníkà 26:16) Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà nìkan ló láṣẹ láti sun tùràrí. Nígbà tí olórí àlùfáà gbìyànjú láti dá Ùsáyà lẹ́kun, ńṣe lọba yìí fárí gá. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀tẹ̀ yọ ní iwájú orí rẹ̀ . . . nítorí pé Jèhófà ti kọlù ú. Ùsáyà Ọba sì ń bá a lọ ní jíjẹ́ adẹ́tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.”—2 Kíróníkà 26:19-21.
6. (a) Kí ló mú kí Sọ́ọ̀lù àti Ùsáyà ta ko ìmọ̀ràn? (b) Kí nìdí tí títa ko ìmọ̀ràn fi jẹ́ ìṣòro ńlá lóde òní?
6 Kí ló jẹ́ kó ṣòro fún Sọ́ọ̀lù àti Ùsáyà láti gba ìmọ̀ràn? Ìgbéraga ló fà á, àwọn méjèèjì ti jọ ara wọn lójú jù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fi ìwà yìí kó ìbànújẹ́ bá ara wọn. Ó jọ pé wọ́n máa ń rò pé bí àwọn bá tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn a jẹ́ pé àbùkù kan ń bẹ lára àwọn tàbí pé àwọn ti tẹ́ nìyẹn. Bẹ́ẹ̀, ìgbéraga gan-an ló jẹ́ àbùkù. Ìgbéraga kì í jẹ́ kéèyàn lè ronú dáadáa, ó sì máa ń múni fẹ́ máa ta ko ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò àjọ rẹ̀. Ìyẹn ni Jèhófà fi kìlọ̀ pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.”—Òwe 16:18; Róòmù 12:3.
Ó Yẹ Ká Máa Tẹ́wọ́ Gba Ìmọ̀ràn
7. Ẹ̀kọ́ rere wo la lè rí kọ́ látinú ìṣarasíhùwà Mósè sí ìmọ̀ràn?
7 Àpẹẹrẹ rere tún wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa àwọn tó tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn, ìwọ̀nyẹn sì lè kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. Wo àpẹẹrẹ ti Mósè, ẹni tí àna rẹ̀ fún nímọ̀ràn nípa bó ṣe lè bójú tó ẹrù iṣẹ́ bàǹtà banta tó ń gbé. Mósè gba ìmọ̀ràn rẹ̀ ó sì fi sílò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. (Ẹ́kísódù 18:13-24) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pá àṣẹ ńlá ń bẹ lọ́wọ́ Mósè, kí nìdí tó fi tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn? Ìdí rẹ̀ ni pé ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. “Mósè sì fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.” (Númérì 12:3) Báwo ni jíjẹ́ ọlọ́kàn tútù ti ṣe pàtàkì tó? Sefanáyà 2:3 fi hàn pé ó lè gba ẹ̀mí wa là.
8. (a) Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Dáfídì dá? (b) Kí ni ìṣarasíhùwà Dáfídì sí ìbáwí Nátánì? (d) Kí ni àbáyọrí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì?
8 Dáfídì Ọba ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà, ó sì ṣekú 2 Sámúẹ́lì 12:13) Lóòótọ́, Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ìrònúpìwàdà Dáfídì, àmọ́ kò ní ṣàì jìyà àfọwọ́fà rẹ̀. Jèhófà sọ fún un pé idà “kì yóò lọ kúrò ní ilé [rẹ̀],” pé àwọn aya rẹ̀ yóò di ti “ọmọnìkejì” rẹ̀, àti pé ọmọ tó fi panṣágà bí yẹn yóò “kú dájúdájú.”—2 Sámúẹ́lì 12:10, 11, 14.
pa Ùráyà ọkọ rẹ̀ láti lè bo panṣágà yẹn mọ́lẹ̀. Jèhófà wá rán Nátánì wòlíì láti lọ bá Dáfídì wí. Dáfídì ronú pìwà dà ó sì jẹ́wọ́ kíákíá pé: “Èmi ti ṣẹ̀ sí Jèhófà.” (9. Kí ni ká má ṣe gbàgbé nígbàkigbà tí wọ́n bá fún wa nímọ̀ràn tàbí tí wọ́n bá bá wa wí?
9 Dáfídì Ọba mọ àǹfààní gbígba ìmọ̀ràn tó yè kooro. Nígbà kan, ńṣe ló dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún rírán ẹni tó rán láti fún òun nímọ̀ràn. (1 Sámúẹ́lì 25:32-35) Ṣé irú èèyàn bẹ́ẹ̀ làwa náà jẹ́? Bí a bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kò ní jẹ́ ká lè máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tàbí ká máa ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tí a óò kábàámọ̀. Ṣùgbọ́n bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé a bọ́ sínú ipò kan tó lè mú ká dẹni tá a máa fún nímọ̀ràn tàbí ẹni tá a tiẹ̀ máa bá wí ń kọ́? Ǹjẹ́ ká má ṣe gbàgbé o, pé èyí jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa, nítorí ó ń fẹ́ kí á jèrè ìyè ayérayé lọ́jọ́ iwájú.—Òwe 3:11, 12; 4:13.
Àwọn Ànímọ́ Iyebíye Tó Yẹ Ká Ní
10. Ànímọ́ wo ni Jésù sọ pé ó ṣe pàtàkì pé kí ẹni tó bá máa jogún Ìjọba Ọlọ́run ní?
10 Láti lè ní àjọṣe tó dán mọ́ràn pẹ̀lú Jèhófà àti àwọn Kristẹni ará wa, ó yẹ kí á fi àwọn ànímọ́ kan kọ́ra. Jésù mẹ́nu kan ọ̀kan nínú wọn nígbà tó pe ọmọ kékeré kan sáàárín àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó sì wá sọ pé: “Láìjẹ́ pé ẹ yí padà, kí ẹ sì dà bí àwọn ọmọ kéékèèké, ẹ kì yóò wọ ìjọba ọ̀run lọ́nàkọnà. Nítorí náà, ẹnì yòówù tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọ kékeré yìí ni ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú ìjọba ọ̀run.” (Mátíù 18:3, 4) Ó yẹ kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kọ́ra, nítorí bí wọ́n ṣe ń bá ara wọn jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn.—Lúùkù 22:24-27.
11. (a) Iwájú ta ló yẹ kí á ti rẹ ara wa sílẹ̀, kí sì nìdí rẹ̀? (b) Bí a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ìhà wo ni a óò máa kọ sí ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún wa?
11 Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Gbogbo yín, ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (1 Pétérù 5:5) A mọ̀ pé a ní láti rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fi hàn pé ó tún yẹ ká rẹ ara wa sílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa pẹ̀lú. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní máa kọ àwọn àbá dáadáa tí àwọn ará bá fún wa, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni a óò máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ wọn.—Òwe 12:15.
12. (a) Ànímọ́ pàtàkì wo ló wé mọ́ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kí a máa ṣàníyàn nípa ipa tí ìwà wa lè ní lórí ọmọnìkejì wa?
12 Ohun kan tó tún wé mọ́ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni jíjẹ́ kí ire ọmọnìkejì jẹni lógún. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì. . . . Nítorí náà, yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run. Ẹ máa fà sẹ́yìn kúrò nínú dídi okùnfà ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì pẹ̀lú àti fún ìjọ Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 10:24-33) Pọ́ọ̀lù ò sọ pé kí á kúkú gbàgbé ohun tó jẹ mọ́ èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́. Ńṣe ló ń rọ̀ wá pé kí á má ṣe ṣe ohun tó lè ki ẹlòmíràn láyà láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ sọ fún un pé ó lòdì.
13. Àpẹẹrẹ wo ló lè fi hàn bóyá ó mọ́ wa lára láti máa fi ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ sílò?
13 Ǹjẹ́ o máa ń fi ire àwọn ẹlòmíràn ṣáájú ohun
tó wù ọ́? Gbogbo wa ló yẹ kó fi ìyẹn kọ́ra. Onírúurú ọ̀nà ni a lè gbà ṣe é. Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀ràn ti aṣọ wíwọ̀ àti ìmúra. Nǹkan méjèèjì yìí jẹ mọ́ ọ̀ràn tí kálukú yóò ti yan ohun tó wù ú, kìkì kó máà sáà ti ré kọjá ìlànà Ìwé Mímọ́ nípa wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì àti wíwà ní mímọ́ nigín. Ṣùgbọ́n bí o bá mọ̀ pé nítorí bí àwọn aládùúgbò rẹ ṣe rí látilẹ̀wá, ọ̀nà ìwọṣọ àti ìmúra rẹ ń mú kí wọ́n máà fẹ́ gbọ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, ṣe wàá ṣe ìyípadà? Láìsí àní-àní, ríran ọmọnìkejì wa lọ́wọ́ láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun ṣe pàtàkì ju ṣíṣe ohun tó kàn wuni lọ.14. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí á fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí ìgbatẹnirò kọ́ra?
14 Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa jíjẹ́ tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni tí ń gba tí ẹlòmíràn rò, débi pé ó tilẹ̀ wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Jòhánù 13:12-15) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa Jésù pé: “Ẹ pa ẹ̀mí ìrònú yìí mọ́ nínú yín, èyí tí ó wà nínú Kristi Jésù pẹ̀lú, ẹni tí ó jẹ́ pé, bí ó tilẹ̀ wà ní ìrísí Ọlọ́run, kò ronú rárá nípa ìjá-nǹkan-gbà, èyíinì ni, pé kí òun bá Ọlọ́run dọ́gba. Ó tì o, ṣùgbọ́n ó sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn. Ju èyíinì lọ, nígbà tí ó rí ara rẹ̀ ní àwọ̀ ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.”—Fílípì 2:5-8; Róòmù 15:2, 3.
Má Ṣe Kọ Ìbáwí Jèhófà
15. (a) Àwọn ìyípadà wo ni a ní láti ṣe láti lè ní ànímọ́ tó wu Ọlọ́run? (b) Kí ni Jèhófà ń lò láti fi pèsè ìmọ̀ràn àti ìbáwí fún gbogbo wa?
15 Nítorí pé gbogbo wa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ó di dandan pé ká yí ìwà àti ìṣe wa padà bí a óò bá máa gbé ànímọ́ Ọlọ́run wa yọ. A ní láti gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀. (Kólósè 3:) Ìmọ̀ràn àti ìbáwí máa ń jẹ́ ká lè mọ ibi tó ti yẹ ká ṣe àwọn àtúnṣe, àti láti mọ ọ̀nà tá a lè gbà ṣe wọ́n. Bíbélì ni orísun pàtàkì tí a ti lè rí ìtọ́ni tí a nílò gbà. ( 5-142 Tímótì 3:16, 17) Àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì àti àwọn ìpàdé tí ètò àjọ Jèhófà ń ṣètò ń ràn wá lọ́wọ́ kí á lè máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. Kódà bó bá tiẹ̀ jẹ́ ìmọ̀ràn tí a ti gbọ́ rí, ṣé a ó ṣì gbà pé a nílò rẹ̀ kí á sì gbìyànjú láti jẹ́ kó mú wa túbọ̀ tẹ̀ síwájú sí i?
16. Ìrànlọ́wọ́ wo ni Jèhófà ń pèsè fún olúkúlùkù wa?
16 Tìfẹ́tìfẹ́ ni Jèhófà fi ń ṣaájò wa tó sì ń ràn wá lọ́wọ́ nípa àwọn ìṣòro wa. Ọ̀kẹ́ àìmọye ni a ti fi ẹ̀kọ́ Bíbélì tí à ń bá wọn ṣe nílé wọn ṣèrànwọ́ fún. Àwọn òbí ń fún àwọn ọmọ wọn nímọ̀ràn wọ́n sì ń bá wọn wí láti lè kó wọn yọ lọ́wọ́ àwọn ìwà tó lè yọrí sí ìbànújẹ́. (Òwe 6:20-23) Nínú ìjọ, àwọn ará sábà máa ń lọ gba ìmọ̀ràn àti àbá lọ́dọ̀ àwọn òjíṣẹ́ tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ tẹ̀ síwájú sí i nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn lóde ẹ̀rí. Nígbà mìíràn, àwọn alàgbà lè béèrè fún ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ara wọn tàbí lọ́dọ̀ àwọn ará yòókù tó nírìírí nínú iṣẹ́ ìsìn. Àwọn tí wọ́n tóótun nípa tẹ̀mí máa ń lo Bíbélì láti fúnni nímọ̀ràn, wọ́n a sì máa fi ọkàn tútù ṣe é. Bí o bá sì ń fúnni nímọ̀ràn, rántí láti máa ‘ṣọ́ ara rẹ lójú méjèèjì, kí a má bàa dẹ ìwọ náà wò.’ (Gálátíà 6:1, 2) Bẹ́ẹ̀ ni o, gbogbo wa la nílò ìmọ̀ràn àti ìbáwí láti lè máa fi ìṣọ̀kan sin Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.
Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò
• Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ibi tó ti yẹ ká ṣe àwọn àtúnṣe?
• Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn tó yẹ, báwo lèyí sì ṣe léwu tó?
• Àwọn ànímọ́ iyebíye wo ni yóò mú ká dẹni tó ń gba ìmọ̀ràn, báwo ni Jésù sì ṣe fí àpẹẹrẹ àwọn ànímọ́ yìí lélẹ̀?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 142]
Ùsáyà kọ ìmọ̀ràn ló bá di adẹ́tẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 142]
Gbígbà tí Mósè gba ìmọ̀ràn Jẹ́tírò ṣe é láǹfààní