Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fi Ìfọkànsin Ọlọ́run Ṣèwà Hù Nínú Ilé

Fi Ìfọkànsin Ọlọ́run Ṣèwà Hù Nínú Ilé

Orí Kẹtàdínlógún

Fi Ìfọkànsin Ọlọ́run Ṣèwà Hù Nínú Ilé

1. Àǹfààní wo ni títẹ̀lé ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ṣe fún ìgbéyàwó?

JÈHÓFÀ ni Ẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì pèsè ìlànà tó dára jù lọ fún ìdílé. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ìgbéyàwó wọn ti kẹ́sẹ járí nítorí pé wọ́n tẹ̀ lé ìlànà yẹn. Ó dùn mọ́ni nínú pé àwọn kan tí wọ́n wulẹ̀ ń gbé pọ̀ tẹ́lẹ̀ ti lọ fìdí ìgbéyàwó wọn múlẹ̀ lábẹ́ òfin. Àwọn kan ti jáwọ́ nínú níní ìbálòpọ̀ lẹ́yìn òde ìgbéyàwó. Àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n máa ń lu aya àtàwọn ọmọ wọn nílùkulù tẹ́lẹ̀ ti kọ́ béèyàn ṣe ń jẹ́ onínúure, tó sì ń báni kẹ́dùn.

2. Kí ni ìgbésí ayé ìdílé Kristẹni wé mọ́?

2 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wé mọ́ ìgbésí ayé ìdílé Kristẹni, bí irú ojú tá a fi ń wo wíwà pẹ́ títí ìgbéyàwó, bá a ṣe ń ṣe ojúṣe tiwa nínú ìdílé, àti bá a ṣe ń ṣe sí àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa. (Éfésù 5:33–6:4) Ọ̀tọ̀ ni kéèyàn mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìgbésí ayé ìdílé, ọ̀tọ̀ sì ni kéèyàn máa fi ìmọ̀ràn inú Bíbélì ọ̀hún ṣèwà hù. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó fẹ́ dà bí àwọn tí Jésù dá lẹ́bi pé wọ́n gbójú fo àwọn àṣẹ Ọlọ́run dá, tí wọ́n ń tan ara wọn jẹ pé táwọn bá ṣáà ti jẹ́ olùfọkànsìn lójú méjèèjì, ó ti tó. (Mátíù 15:4-9) A kò fẹ́ jẹ́ olùfọkànsin Ọlọ́run àmọ́ ká máà wá fi ìfọkànsin Ọlọ́run ọ̀hún ṣèwà hù nínú agbo ilé tiwa. Kàkà bẹ́ẹ̀ a fẹ́ fi ìfọkànsin Ọlọ́run, tí ó “jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá,” hàn nínú ayé wa.—1 Tímótì 5:4; 6:6; 2 Tímótì 3:5.

Báwo Ló Se Yẹ Kí Ìgbéyàwó Pẹ́ Tó?

3. (a) Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó, àmọ́ kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa? (b) Lo Bíbélì rẹ láti dáhùn àwọn ìbéèrè tá a tó sísàlẹ̀ ìpínrọ̀ yìí.

3 Ńṣe ni ìdè ìgbéyàwó túbọ̀ ń di ohun ẹlẹgẹ́ sí i. Àwọn tọkọtaya kan tó ti wà pa pọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún pinnu láti kọ ara wọn sílẹ̀ láti fẹ́ ẹlòmíràn. Bẹ́ẹ̀ náà ni kì í ṣe nǹkan àjèjì mọ́ láti gbọ́ pé àwọn tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ti pínyà lẹ́yìn tí wọ́n jọ gbé fún ìwọ̀nba àkókò díẹ̀. Ohun yòówù káwọn ẹlòmíì máa ṣe, àwa gbọ́dọ̀ fẹ́ láti múnú Jèhófà dùn. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká yẹ àwọn ìbéèrè àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí wò láti rí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa bí ìgbéyàwó ṣe lè wà pẹ́ títí.

Nígbà tí ọkùnrin àtobìnrin bá ṣe ìgbéyàwó, báwo ló ṣe yẹ kí gbígbé pọ̀ wọn pẹ́ tó? (Máàkù 10:6-9; Róòmù 7:2, 3)

Kí ni ìdí kan ṣoṣo tí Ọlọ́run fọwọ́ sí pé èèyàn lè tìtorí rẹ̀ kọ ọkọ tàbí aya rẹ̀ sílẹ̀, kó sì fẹ́ ẹlòmíràn? (Mátíù 5:31, 32; 19:3-9)

Ojú wo ni Jèhófà fi wo ìkọ̀sílẹ̀ tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò fàyè gbà? (Málákì 2:13-16)

Ǹjẹ́ Bíbélì fọwọ́ sí ìpínyà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tá a fi lè yanjú àwọn ìṣòro inú ìgbéyàwó? (1 Kọ́ríńtì 7:10-13)

Àwọn ipò wo ló lè mú ká fàyè gba ìpínyà? (Sáàmù 11:5; Lúùkù 4:8; 1 Tímótì 5:8)

4. Kí nìdí táwọn ìgbéyàwó kan fi ń wà pẹ́ títí?

4 Àwọn ìgbéyàwó kan kẹ́sẹ járí, tí àwọn tọkọtaya náà sì ti ń gbé pọ̀ tipẹ́. Ki nìdí? Dídúró dìgbà táwọn méjèèjì dàgbà dénú kí wọ́n tó ṣe ìgbéyàwó jẹ́ kókó kan, àmọ́ rírí ọkọ tàbí aya tó fẹ́ ohun téèyàn fẹ́, tá a sì lè jọ jíròrò fàlàlà tún ṣe pàtàkì. Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé kẹ́ni téèyàn á rí fẹ́ jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tó sì bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ohun tá a lè fi yanjú àwọn ìṣòro. (Sáàmù 119:97, 104; 2 Tímótì 3:16, 17) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní í ní ẹ̀mí pé bí nǹkan kò bá ṣẹnuure, òun lè pínyà tàbí kóun jáwèé ìkọ̀sílẹ̀. Kò ní kọ̀ láti ṣe ojúṣe tirẹ̀ nítorí pé ọkọ tàbí aya rẹ̀ kù síbì kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, yóò kojú àwọn ìṣòro tó bá dìde, yóò sì wá bóun ṣe máa yanjú wọn lọ́nà tó dáa.

5. (a) Ipa wo ni ìdúróṣinṣin sí Jèhófà ń kó nínú ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó? (b) Kódà nígbà tá a bá dojú kọ àtakò, kí làwọn àǹfààní tí títẹ̀lé ìlànà Jèhófà lè mú wá?

5 Sátánì sọ pé tí ìyà bá jẹ wá, a ó fi àwọn ọ̀nà Jèhófà sílẹ̀. (Jóòbù 2:4, 5; Òwe 27:11) Àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti jìyà nítorí níní ọkọ tàbí aya tó lòdì sí wọn kò kọ ẹnì kejì wọn sílẹ̀. Wọ́n ń bá a lọ ní jíjẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àtàwọn àṣẹ rẹ̀. (Mátíù 5:37) Àwọn kan tó fara dà á ti wá ń yọ̀ báyìí pé ẹni kejì wọn ti dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìjọsìn Jèhófà—kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tó ti fi ṣàtakò! (1 Pétérù 3:1, 2) Ní ti àwọn Kristẹni tí ọkọ tàbí aya wọn kò fẹ́ yí padà rárá tàbí tí ọkọ tàbí aya wọn ti fi wọ́n sílẹ̀ nítorí pé wọ́n ń sin Jèhófà, àwọn náà mọ̀ pé a ó bù kún wọn nítorí fífi tí wọ́n ń fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣèwà hù nínú ilé.—Sáàmù 55:22; 145:16.

Olúkúlùkù Ń Ṣe Ipa Tirẹ̀

6. Tá a bá fẹ́ kí ìgbéyàwó wa kẹ́sẹ járí, ètò wo la gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún?

6 Ká sọ tòótọ́, gbígbé pa pọ̀ nìkan kọ́ la fi ń sọ pé ìgbéyàwó kẹ́sẹ járí. Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni kí tọkọtaya bọ̀wọ̀ fún ètò tí Jèhófà ṣe nípa ipò orí. Èyí ń jẹ́ kí nǹkan wà létòlétò, ó sì ń jẹ́ kí ọkàn èèyàn balẹ̀ nínú ilé. Ìwé 1 Kọ́ríńtì 11:3 kà pé: “Orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.”

7. Báwo lo ṣe yẹ kí ọkọ lo ipò orí nínú ìdílé?

7 Ǹjẹ́ o kíyè sí ohun tí ẹsẹ yẹn kọ́kọ́ mẹ́nu kàn? Bẹ́ẹ̀ ni, olúkúlùkù ọkùnrin ló ní Orí, ìyẹn Kristi, tí wọ́n gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún. Èyí túmọ̀ sí pé ọkọ ní láti lo ipò orí rẹ̀ lọ́nà tó fi àwọn ànímọ́ Jésù hàn. Kristi tẹrí ba fún Jèhófà, ó nífẹ̀ẹ́ ìjọ gan-an, ó sì bójú tó o. (1 Tímótì 3:15) Ó tiẹ̀ “jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un” pàápàá. Jésù kì í ṣe agbéraga tí kì í gba tẹni rò, àmọ́ ó jẹ́ “onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà.” Àwọn tó wá sábẹ́ ipò orí rẹ̀ “rí ìtura fún ọkàn [wọn].” Nígbà tí ọkọ kan bá ń bá ìdílé rẹ̀ lò lọ́nà yìí, ó ń fi hàn pé òun ń tẹrí ba fún Kristi. Ó yẹ kí èyí mú kí Kristẹni aya kan rí i pé yóò ṣe òun láǹfààní, yóò sì tu òun lára bí òun bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ òun, tí òun sì ń tẹrí ba fún ipò orí rẹ̀.—Éfésù 5:25-33; Mátíù 11:28, 29; Òwe 31:10, 28.

8. (a) Kí nìdí tó fi lè dà bíi pé títẹ̀lé àwọn ọ̀nà Kristẹni kò ṣàṣeyọrí tá a fẹ́ láwọn ilé kan? (b) Kí la lè ṣe tá a bá dojú kọ irú ipò bẹ́ẹ̀?

8 Àmọ́ ṣá o, ìṣòro ò lè ṣe kó má yọjú. Kí ẹlòmíràn máa darí ẹni nínú ilé ti lè máa fa ìbínú tí kò ṣeé fẹnu sọ kó tó di pé ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé náà bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Fífi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè nǹkan àti fífi ìfẹ́ hàn lè jọ bí èyí tí kò ṣe àṣeyọrí kankan. A mọ̀ pé Bíbélì ní kí a mú “ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú” kúrò. (Éfésù 4:31) Àmọ́ bí àwọn kan nínú ìdílé kò bá mọ̀ ju ká jágbe mọ́ni ńkọ́, kí la lè ṣe? Tóò, Jésù kò fara wé àwọn tó ń halẹ̀, tí wọ́n sì ń kẹ́gàn, àmọ́ ó gbára lé Baba rẹ̀. (1 Pétérù 2:22, 23) Nítorí náà, nígbà tí ipò nǹkan bá le koko nínú ilé, fi ẹ̀rí ìfọkànsin Ọlọ́run hàn nípa gbígbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ dípò tí wàá fi máa tẹ̀ lé àwọn ọ̀nà ayé.—Òwe 3:5-7.

9. Dípò wíwá ẹ̀sùn síni lẹ́sẹ̀, kí ni ọ̀pọ̀ ọkọ Kristẹni kọ́ láti ṣe?

9 Ipò nǹkan kò lè yí padà lójú ẹsẹ̀, àmọ́ ìmọ̀ràn Bíbélì máa ń gbéṣẹ́ nígbà tá a bá fi sùúrù àti aápọn mú un lò. Ọ̀pọ̀ ọkọ ló ti rí i pé ìgbéyàwó àwọn bẹ̀rẹ̀ sí sunwọ̀n sí i nígbà tí wọ́n wá lóye ọ̀nà tí Kristi gbà bá ìjọ lò. Kì í ṣe àwọn ẹni pípé ló wà nínú ìjọ yẹn. Síbẹ̀, Jésù nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún un, ó sì ń lo Ìwé Mímọ́ láti ràn án lọ́wọ́ kí ó lè sunwọ̀n sí i. Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ìjọ. (1 Pétérù 2:21) Àpẹẹrẹ rẹ̀ ti fún ọ̀pọ̀ Kristẹni ọkọ níṣìírí láti jẹ́ olórí ìdílé tó dáńgájíá, tó sì ń fìfẹ́ ṣèrànwọ́ láti mú kí ìgbéyàwó wọn sunwọ̀n sí i. Èyí ń mú àbájáde tó dára gan-an wá ju wíwá ẹ̀sùn síni lẹ́sẹ̀ tàbí dídákẹ́ láìsọ̀rọ̀ lọ.

10. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni ọkọ tàbí aya kan—kódà ẹni tó pera rẹ̀ ní Kristẹni pàápàá—fi lè máyé sú àwọn mìíràn nínú ilé? (b) Kí la lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà?

10 Bí ọkọ kan kò bá bìkítà nípa ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ ńkọ́ tàbí tí kì í lo ìdánúṣe láti ṣètò bí ìdílé ṣe máa jíròrò Bíbélì àti bí wọ́n ṣe máa ṣe àwọn ìgbòkègbodò mìíràn? Tàbí bí aya kan kì í bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, tí kò sì ní ìtẹríba ńkọ́? Àwọn kan ti ṣàṣeyọrí nípa fífi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ jíròrò àwọn ìṣòro ìdílé pa pọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 21:10-12; Òwe 15:22) Kódà bí àbájáde rẹ̀ kò bá tiẹ̀ tó bá a ṣe retí, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe ipa tirẹ̀ láti mú kí ipò nǹkan sunwọ̀n sí i nínú ilé nípa fífi èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run hàn nínú ìgbésí ayé wa, ká sì máa fìfẹ́ gba tàwọn mẹ́ńbà ìdílé wa yòókù rò. (Gálátíà 5:22, 23) Kì í ṣe dídúró de ẹlòmíràn láti ṣe ohun kan ló máa mú ìtẹ̀síwájú wá, bí kò ṣe nípa ṣíṣe ipa tiwa, ká sì máa tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a ń fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣèwà hù.—Kólósè 3:18-21.

Ibi Tá A Ti Lè Rí Ìdáhùn

11, 12. Kí ni Jèhófà pèsè láti fi ràn wá lọ́wọ́ kí ìgbésí ayé ìdílé wa lè dára?

11 Àwọn ọ̀nà pọ̀ táwọn èèyàn máa ń yíjú sí láti gbàmọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìdílé wọn. Síbẹ̀, a mọ̀ pé inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìmọ̀ràn tó dára jù lọ wà, inú wa sì dùn pé Ọlọ́run ń tipasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀ tá a lè fojú rí ràn wá lọ́wọ́ láti mú un lò. Ṣé ò ń jàǹfààní ní kíkún látinú ìrànlọ́wọ́ yẹn?—Sáàmù 119:129, 130; Míkà 4:2.

12 Ní àfikún sí lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, ǹjẹ́ o ti ṣètò àkókò fún ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìdílé rẹ déédéé? Àwọn ìdílé tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ lè wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn wọn. Ìgbésí ayé ìdílé wọn ń dára sí i bí wọ́n ṣe ń mú ipò wọn bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu.—Diutarónómì 11:18-21.

13. (a) Bí a bá ní àwọn ìbéèrè lórí ọ̀ràn ìdílé, ibo la ti lè rí ìrànlọ́wọ́ tá a nílò? (b) Kí la gbọ́dọ̀ máa fi hàn nínú gbogbo ìpinnu tá a bá ṣe?

13 O lè ní àwọn ìbéèrè lórí ọ̀ràn ìdílé. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ nípa ìfètò-sọ́mọ-bíbí ńkọ́? Ǹjẹ́ a tiẹ̀ rí ìgbà tí oyún ṣíṣẹ́ dára? Bí ọmọ kan kò bá fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tẹ̀mí ńkọ́, báwo la ṣe lè retí pé kó máa kópa nínú ìjọsìn ìdílé tó? Ọ̀pọ̀ irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ la ti jíròrò nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde. Kọ́ bí a ṣe ń lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, títí kan atọ́ka, láti wá ìdáhùn rí. Bí o kò bá ní àwọn ìwé tí atọ́ka darí rẹ sí, yẹ ibi ìkówèésí wò ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Tàbí kẹ̀, o lè rí àwọn ìwé wọ̀nyí nínú kọ̀ǹpútà rẹ. O sì tún lè jíròrò àwọn ìbéèrè rẹ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin àtobìnrin Kristẹni tó dàgbà dénú. Àmọ́ ṣá o, má máa fi gbogbo ìgbà retí àtigbọ́ bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ sí gbogbo ìbéèrè rẹ. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ìwọ lo máa ṣe ìpinnu, yálà ní ìwọ nìkan tàbí gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya. Nítorí náà, rí i pé o ṣe àwọn ìpinnu tó máa fi hàn pé bí o ṣe ń fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣèwà hù ní gbangba náà ni o fi ń ṣèwà hù nínú ilé.—Róòmù 14:19; Éfésù 5:10.

Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò

• Báwo ni ìdúróṣinṣin sí Jèhófà ṣe kan jíjẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya ẹni?

• Nígbà tí wàhálà bá dé nítorí àwọn ìṣòro ìdílé, kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó ń múnú Ọlọ́run dùn?

• Kódà bí àwọn mìíràn nínú ìdílé kò bá ṣe tó bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe, kí la lè ṣe láti mú kí ipò náà sunwọ̀n sí i?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 155]

Ipò orí ọkọ gbọ́dọ̀ fi àwọn ànímọ́ Jésù hàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 157]

Ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé pẹ̀lú ìdílé ń ṣèrànwọ́ láti mú ìdílé wà níṣọ̀kan