Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
Orí Ogún
Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
1. Nígbà tó o kọ́kọ́ gbọ́ pé ìdáǹdè kúrò nínú ìbànújẹ́ ètò ògbólógbòó yìí ti sún mọ́lé, báwo ló ṣe rí lára rẹ̀?
Ọ̀KAN lára ohun tó o kọ́kọ́ kọ́ nínú Bíbélì ni pé ète Jèhófà ni kí gbogbo ayé di Párádísè. Nínú ayé tuntun yẹn, kò ní sí ogun, ìwà ọ̀daràn, ipò òṣì, àìsàn, ìrora, àti ikú mọ́. Kódà àwọn tó ti kú yóò padà wà láàyè. Ìfojúsọ́nà àgbàyanu mà lèyí o! Ohun tó fi hàn pé gbogbo èyí ti sún mọ́ tòsí ni wíwàníhìn-ín Kristi gẹ́gẹ́ bí Ọba tí a kò lè fojú rí tó bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1914, àti pé a ti wà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé búburú yìí látìgbà yẹn. Ní òpin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, Jèhófà yóò pa ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí run, yóò sì mú ayé tuntun tó ṣèlérí wá!
2. Kí ni “ọjọ́ Jèhófà”?
2 Bíbélì pe àkókò ìparun tó ń bọ̀ yìí ní “ọjọ́ Jèhófà.” (2 Pétérù 3:10) Ó jẹ́ “ọjọ́ ìbínú Jèhófà” lórí gbogbo ayé Sátánì. (Sefanáyà 2:3) Yóò dé òtéńté rẹ̀ ní “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè . . . , tí à ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì [Amágẹ́dọ́nì] lédè Hébérù,” nínú èyí tí a ó ti pa “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé pátá” rẹ́ ráúráú. (Ìṣípayá 16:14, 16) Ǹjẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ fi hàn pé ó dá ọ lójú pé “ọjọ́ Jèhófà” tá à ń wí yìí ti sún mọ́lé?—Sefanáyà 1:14-18; Jeremáyà 25:33.
3. (a) Ìgbà wo ni ọjọ́ Jèhófà yóò dé? (b) Àǹfààní wo ló wà nínú bí Jèhófà kò ṣe ṣí “ọjọ́ yẹn tàbí wákàtí náà” payá fún wa?
3 Bíbélì kò sọ fún wa nípa ọjọ́ náà pàtó tí Jésù Máàkù 13:32) Bí àwọn kan kò bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú, wọ́n á fẹ́ máa sún ọjọ́ rẹ̀ síwájú nínú ọkàn wọn, wọ́n á sì máa lépa àtijẹ àtimu kiri. Ṣùgbọ́n àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lóòótọ́ yóò fi tọkàntọkàn sìn ín, láìka ìgbà tí òpin ètò búburú yìí yóò dé sí.—Sáàmù 37:4; 1 Jòhánù 5:3.
Kristi yóò dé gẹ́gẹ́ bí Amúdàájọ́ Jèhófà ṣẹ sórí ètò àwọn nǹkan Sátánì. Jésù sọ pé: “Ní ti ọjọ́ yẹn tàbí wákàtí náà, kò sí ẹni tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba.” (4. Kí ni Jésù sọ gẹ́gẹ́ bí ìkìlọ̀?
4 Nínú ìkìlọ̀ tí Jésù ṣe fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sọ pé: “Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́.” (Máàkù 13:33-37) Ó rọ̀ wá pé kí a má ṣe jẹ́ kí jíjẹ àti mímu tàbí “àwọn àníyàn ìgbésí ayé” gba àfiyèsí wa jù débi tá a ó fi gbàgbé ìjẹ́pàtàkì àwọn àkókò.—Lúùkù 21:34-36; Mátíù 24:37-42.
5. Bí Pétérù ṣe ṣàlàyé, kí ni ọjọ́ Jèhófà yóò mú wá?
5 Bákan náà ni Pétérù gbà wá nímọ̀ràn pé ká fi “wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà” sọ́kàn “nípasẹ̀ èyí tí àwọn ọ̀run tí wọ́n ti gbiná yóò di yíyọ́, tí àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò sì yọ́.” Gbogbo ìjọba ènìyàn, ìyẹn “àwọn ọ̀run” yóò pa run, àti gbogbo àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn burúkú lápapọ̀, ìyẹn “ayé” àti “àwọn ohun ìpìlẹ̀” inú rẹ̀, èyí tí í ṣe àwọn èrò àti ìṣe ayé búburú yìí, irú bí ẹ̀mí kíkọ̀ láti jẹ́ kí Ọlọ́run darí ẹni, ìṣekúṣe àti ìgbésí ayé onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì rẹ̀. Ohun tí yóò sì rọ́pò ìwọ̀nyí ni “ọ̀run tuntun [ìyẹn Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run] àti ilẹ̀ ayé tuntun [ìyẹn àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn 2 Pétérù 3:10-13) Àwọn àjálù tó máa dé bá ayé yìí yóò ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ àti wákàtí tí a kò retí.—Mátíù 24:44.
tuntun]” nínú èyí tí “òdodo yóò . . . máa gbé.” (Ẹ Wà Lójúfò sí Àmì Náà
6. (a) Báwo ni ìmúṣẹ èsì Jésù sí ìbéèrè àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe gbòòrò tó nígbà ètò nǹkan àwọn Júù? (b) Apá wo nínú ìdáhùn Jésù ló darí àfiyèsí sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ìṣarasíhùwà tó bẹ̀rẹ̀ látọdún 1914 síwájú?
6 Lójú bí àkókò tí à ń gbé ṣe rí, ó yẹ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àmì náà èyí tó ní oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ nínú, èyí tó sàmì sí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ìyẹn “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Rántí pé nígbà tí Jésù dáhùn ìbéèrè tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè, èyí tó wà nínú Mátíù 24:3, àwọn kan lára ohun tó ṣàpèjúwe ní ẹsẹ ìkẹrin sí ìkejìlélógún ní ìmúṣẹ kékeré sórí ètò àwọn Júù láàárín ọdún 33 sí 70 Sànmánì Tiwa. Àmọ́ àsọtẹ́lẹ̀ náà ní lájorí ìmúṣẹ rẹ̀ láti sáà tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914, ìyẹn àkókò “wíwàníhìn-ín” Kristi “àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan.” Mátíù 24:23-28 sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ láti ọdún 70 Sànmánì Tiwa títí di àkókò wíwàníhìn-ín Kristi. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tá a ṣàpèjúwe wọn nínú Mátíù 24:29–25:46 wáyé ní àkókò òpin.
7. (a) Èé ṣe tó fi yẹ kí àwa fúnra wa wà lójúfò sí bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ ṣe ń mú àwọn àmì náà ṣẹ? (b) Dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà ní òpin ìpínrọ̀ yìí, tó ń fi bí àmì náà ti ṣe nímùúṣẹ láti ọdún 1914 hàn.
7 Ó yẹ kí àwa fúnra wa máa kíyè sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ìṣarasíhùwà tó mú àmì yẹn ṣẹ. Síso àwọn nǹkan wọ̀nyí pọ̀ mọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn. Yóò sì tún ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bí a ṣe ń yíni lérò padà nígbà tá a bá ń kìlọ̀ fáwọn Aísáyà 61:1, 2) Pẹ̀lú àwọn kókó wọ̀nyí lọ́kàn, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí, èyí tó fi àwọn apá ti àmì náà ní hàn, bó ṣe wà nínú Mátíù 24:7 àti Lúùkù 21:10, 11.
ẹlòmíràn nípa bí ọjọ́ náà ṣe sún mọ́lé tó. (Ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa dídìde tí “orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba” gbà bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ látọdún 1914? Ní ti ọ̀ràn ogun, kí ló ti ṣẹlẹ̀ látìgbà yẹn?
Ní ọdún 1918, àjàkálẹ̀ àrùn wo ló pa àwọn èèyàn tó pọ̀ ju ohun tí Ogun Àgbáyé Kìíní pa lọ? Láìfi ìmọ̀ ìṣègùn tí àwọn èèyàn ní pè, àrùn wo ló ṣì ń pa ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn?
Láìfi ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ọ̀rúndún tó kọjá pè, báwo ni àìtó oúnjẹ ṣe nípa lórí ayé tó?
Kí ló mú un dá ọ lójú pé kì í ṣe bí nǹkan ṣe rí látìbẹ̀rẹ̀ ayé ni 2 Tímótì 3:1-5, 13 ń ṣàpèjúwe rẹ̀, bí kò ṣe bí àwọn ipò búburú ṣe ń gbilẹ̀ sí i bá a ṣe ń sún mọ́ òpin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn?
Yíya Àwọn Èèyàn Sọ́tọ̀
8. (a) Kí ni nǹkan mìíràn tá a ṣàpèjúwe nínú Mátíù 13:24-30, 36-43, tí Jésù so pọ̀ mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan? (b) Kí ni àpèjúwe Jésù túmọ̀ sí?
8 Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì mìíràn tún wà tí Jésù so pọ̀ mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Ọ̀kan lára ìwọ̀nyí ni yíya “àwọn ọmọ ìjọba náà” kúrò lára “àwọn ọmọ ẹni burúkú náà.” Jésù sọ̀rọ̀ nípa èyí nínú àkàwé rẹ̀ nípa oko àlìkámà tí ọ̀tá kan wá gbin àwọn èpò sí. “Àlìkámà” nínú àpèjúwe rẹ̀ tọ́ka sí àwọn Kristẹni ẹni àmì Mátíù 13:24-30, 36-43) Ǹjẹ́ èyí ti wáyé ní ti gidi?
òróró tòótọ́. “Àwọn èpò” ni àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni, àmọ́ tí wọ́n fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí “ọmọ ẹni burúkú náà” nítorí pé wọ́n dara pọ̀ mọ́ ayé tí Èṣù jẹ́ alákòóso rẹ̀. Àwọn wọ̀nyí la yà sọ́tọ̀ kúrò lára “àwọn ọmọ ìjọba [Ọlọ́run]” a sì ti sàmì sí wọn fún ìparun. (9. (a) Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, ìyàsọ́tọ̀ ńlá wo ló wáyé fún gbogbo àwọn tó pera wọn ní Kristẹni? (b) Báwo làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe fẹ̀rí hàn pé àwọn jẹ́ ìránṣẹ́ tòótọ́ fún Ìjọba náà?
9 Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, a ya gbogbo àwọn tó pera wọn ní Kristẹni sí ẹgbẹ́ méjì: (1) Àwùjọ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn ọmọlẹ́yìn wọn, tí wọ́n sọ ní gbangba pé ẹ̀yìn Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (tá a mọ̀ sí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè báyìí) làwọ́n wà, nígbà tí wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí orílẹ̀-èdè tiwọn, àti (2) àwọn Kristẹni tòótọ́ tó wà ní sànmánì ẹ̀yìn ogun yẹn, tó jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run ti Mèsáyà náà ni wọ́n tì lẹ́yìn gbágbáágbá, wọn kò ti àwọn orílẹ̀-èdè ayé yìí lẹ́yìn. (Jòhánù 17:16) Àwọn wọ̀nyí fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ tòótọ́ fún Ìjọba Ọlọ́run nípa wíwàásù “ìhìn rere ìjọba yìí” jákèjádò ayé. (Mátíù 24:14) Kí ni àbájáde rẹ̀?
10. Kí ni ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà kọ́kọ́ ṣe àṣeyọrí rẹ̀?
10 Èkíní, ìkójọpọ̀ ìyókù àwọn tá a fẹ̀mí Ọlọ́run yàn wáyé, ìyẹn àwọn tí wọ́n ní ìrètí wíwà pẹ̀lú Kristi gẹ́gẹ́ bí apá kan Ìjọba ọ̀run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ wà, síbẹ̀ a mú wọn wá sínú ètò tó ṣọ̀kan. Òpin fífi èdìdì di àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí ti sún mọ́lé.—Ìṣípayá 7:3, 4.
11. (a) Iṣẹ́ ìkójọ wo ló ń bá a lọ, ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ wo sì ni? (b) Kí ni ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí túmọ̀ sí?
Ìṣípayá 7:9, 14; Jòhánù 10:16) Iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run kí òpin tó dé yìí ṣì ń bá a lọ di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí. Ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àgùntàn mìíràn, tí wọ́n ti ń lọ sí ọ̀kẹ́ àìmọye báyìí, ń fi ìdúróṣinṣin ran ìyókù ẹni àmì òróró lọ́wọ́ láti polongo ìhìn pàtàkì ti Ìjọba náà. Àwọn èèyàn sì ń gbọ́ ìhìn yìí ní gbogbo orílẹ̀-èdè.
11 Lẹ́yìn ìyẹn ni ìkójọpọ̀ àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” bẹ̀rẹ̀, lábẹ́ ìdarí Kristi. Àwọn wọ̀nyí ló para pọ̀ jẹ́ “àgùntàn mìíràn” tí yóò la “ìpọ́njú ńlá náà” já sínú ayé tuntun Ọlọ́run. (Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Iwájú?
12. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù tó kù láti ṣe ti pọ̀ tó kí ọjọ́ Jèhófà tóó dé?
12 Gbogbo ẹ̀rí tó wà lókè yìí fi hàn pé a ti ń sún mọ́ òpin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àti pé ọjọ́ Jèhófà ti dé tán. Àmọ́ ṣé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ṣì wà tó máa nímùúṣẹ
kí ọjọ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ yẹn tó bẹ̀rẹ̀ ni? Bẹ́ẹ̀ ni. Kókó kan ni pé, yíya àwọn èèyàn sọ́tọ̀ lórí ọ̀ràn Ìjọba náà kó tíì dópin. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun sì tún ń pọ̀ báyìí láwọn àgbègbè kan tí àtakò líle koko wà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Kódà níbi táwọn èèyàn ti kọ ìhìn rere náà, ẹ̀rí tá à ń jẹ́ ń fi àánú Jèhófà hàn kedere. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá iṣẹ́ náà lọ ní pẹrẹu! Jésù mú un dá wa lójú pé nígbà tí iṣẹ́ náà bá parí, òpin yóò dé.13. Bí ó ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ ìwé 1 Tẹsalóníkà 5:2, 3, ìṣẹ̀lẹ̀ gbígbàfiyèsí wo ló ṣì máa wáyé, kí ni yóò sì túmọ̀ sí fún wa?
13 Àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn tó ṣe pàtàkì gan-an nínú Bíbélì sọ pé: “Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń sọ pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìroragógó wàhálà lórí obìnrin tí ó lóyún; wọn kì yóò sì yè bọ́ lọ́nàkọnà.” (1 Tẹsalóníkà 5:2, 3) Ọ̀nà tí wọ́n máa gbà polongo “àlàáfíà àti ààbò” yẹn la ò tíì mọ̀. Àmọ́, ó dájú pé kò ní túmọ̀ sí pé àwọn aláṣẹ ayé ti yanjú ìṣòro ìran ènìyàn ní ti gidi. Ìpolongo yẹn kò ní tan àwọn tó ń fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn jẹ. Wọn mọ̀ pé kété lẹ́yìn ìyẹn ni ìparun òjijì yóò dé.
14. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni yóò wáyé lákòókò ìpọ́njú ńlá, báwo ni yóò sì ṣe tẹ̀ léra?
14 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá, àwọn alákòóso yóò kọjúùjà sí Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, wọn ó sì pa á rún yán-ányán-án. (Mátíù 24:21; Ìṣípayá 17:15, 16) Lẹ́yìn ìyẹn làwọn orílẹ̀-èdè yóò wá kọjúùjà sáwọn tó ń gbé ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lárugẹ, èyí ni yóò fa ìrunú Jèhófà sórí àwọn ìjọba olóṣèlú àtàwọn alátìlẹyìn wọn, tí yóò sì yọrí sí ìparun wọn yán-ányán-án. Ìyẹn ni Amágẹ́dọ́nì tó máa kásẹ̀ ìpọ́njú ńlá nílẹ̀. Ẹ̀yìn ìyẹn la óò wá ju Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, tí wọn ò ti ní lè nípa lórí aráyé mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ òpin ọjọ́ Jèhófà nígbà tí a ó gbé orúkọ rẹ̀ ga.—Ìsíkíẹ́lì 38:18, 22, 23; Ìṣípayá 19:11–20:3.
15. Èé ṣe tí yóò fi jẹ́ ìwà òmùgọ̀ láti ronú pé ọjọ́ Jèhófà ṣì jìnnà?
15 Òpin ètò nǹkan yìí yóò dé lákòókò tó yẹ kó dé gan-an, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣètò rẹ̀. Kì yóò pẹ́. (Hábákúkù 2:3) Rántí pé ìparun Jerúsálẹ́mù ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa dé lẹ́yẹ-ò-sọkà, nígbà táwọn Júù kò retí rẹ̀, nígbà tí wọ́n rò pé ewu náà ti kọjá. Bábílónì ìgbàanì náà ńkọ́? Ó jẹ́ alágbára, ó dá ara rẹ̀ lójú, ó si ní ògiri gíga tí wọ́n fi mọ odi yí i ká. Àmọ́ òru ọjọ́ kan ló ṣubú. Bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ni ìparun òjijì yóò dé bá ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí. Nígbà tó bá ṣẹlẹ̀, ǹjẹ́ kí a wà ní ìṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́, níwọ̀n bí a ti fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn.
Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò
• Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn? Báwo la ṣe lè ṣèyẹn?
• Báwo ni yíya àwọn èèyàn sọ́tọ̀, tó ń lọ lọ́wọ́, ṣe kàn wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?
• Kí ló kù tó máa ṣẹlẹ̀ kí ọjọ́ Jèhófà tóó dé? Nítorí náà, kí ló yẹ kí àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa ṣe?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwés 180, 181]
Nígbà tí ètò Sátánì bá pa run láìpẹ́ ni àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí yóò dópin