Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Níwájú Ìtẹ́ Jèhófà
Orí Kẹtàlá
Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Níwájú Ìtẹ́ Jèhófà
1. (a) Kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí ń bẹ kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé tàbí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó lè rí èrè wọn gbà, kí ló gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ sí wọn? (b) Kí ni yóò ṣeé ṣe fún “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí ń bẹ láàyè nísinsìnyí?
ÀWỌN olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run látìgbà Ébẹ́lì títí dìgbà Jòhánù Olùbatisí fi ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run sípò kìíní nínú ìgbésí ayé wọn. Síbẹ̀, gbogbo wọn ló kú, tí wọ́n sì ń dúró de àjíǹde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé nínú ayé tuntun Ọlọ́run. Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí yóò bá Kristi jọba nínú Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run pẹ̀lú gbọ́dọ̀ kú kí wọ́n tó lè rí èrè wọn gbà. Àmọ́, Ìṣípayá 7:9 fi hàn pé ní ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” kan látinú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò wà, tí kì yóò kú rárá, ṣùgbọ́n tí yóò ní ìrètí àtiwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ o wà lára wọn?
Dídá Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Náà Mọ̀
2. Báwo ló ṣe wá di pé a ní òye tó ṣe kedere nípa àwọn tí ogunlọ́gọ̀ ńlá inú Ìṣípayá 7:9 jẹ́ gan-an?
2 Ọdún 1923 làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà fòye mọ̀ pé “àwọn àgùntàn” inú àkàwé Jésù nínú ìwé Mátíù 25:31-46 àti “àwọn àgùntàn mìíràn” tó sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Jòhánù 10:16, jẹ́ àwọn èèyàn tí yóò láǹfààní láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ọdún 1931 la mọ̀ pé àwọn tí Ìsíkíẹ́lì 9:1-11 sọ pé a sàmì sí iwájú orí wọn jẹ́ àwọn tó ní ìrètí orí ilẹ̀ ayé. Ìgbà tó wá di ọdún 1935 la rí i pé ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jẹ́ ara ẹgbẹ́ àwọn àgùntàn mìíràn tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Lónìí, ogunlọ́gọ̀ ńlá tá a fi ojú rere hàn sí yìí ti di ọ̀kẹ́ àìmọye.
3. Kí nìdí tí gbólóhùn náà pé wọ́n “dúró níwájú ìtẹ́” kò fi hàn pé èrò ọ̀run ni wọ́n?
3 Ìwé Ìṣípayá 7:9 kò sọ pé ọ̀run ni ogunlọ́gọ̀ ńlá wà. Kò dìgbà tí wọ́n bá wà ní ọ̀run kí wọ́n tó lè “dúró níwájú ìtẹ́” Ọlọ́run. Wọ́n kàn wà níbi tójú Ọlọ́run ti ń wò wọ́n ni. (Sáàmù 11:4) Òtítọ́ náà pé ogunlọ́gọ̀ ńlá, “tí ẹnì kankan kò lè kà,” kì í ṣe èrò ọ̀run hàn kedere bá a bá fi iye wọn tí kò ṣe pàtó wéra pẹ̀lú ohun tó wà nínú Ìṣípayá 7:4-8 àti Ìṣípayá 14:1-4. A fi hàn níbẹ̀ pé iye àwọn èèyàn tá a mú látorí ilẹ̀ ayé lọ sọ́run jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì.
4. (a) Kí ni “ìpọ́njú ńlá” tí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà là já? (b) Gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 7:11, 12 ti wí, àwọn wo ló rí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà, tí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìjọsìn?
4 Ìṣípayá 7:14 sọ nípa ogunlọ́gọ̀ ńlá pé: “Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ó jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà.” Wọ́n la ìpọ́njú tó burú jù lọ nínú ìtàn aráyé já. (Mátíù 24:21) Nígbà tí wọ́n sì ń dúpẹ́ pé ọpẹ́lọpẹ́ Ọlọ́run àti Kristi làwọn fi rí ìgbàlà, ńṣe ni gbogbo ẹ̀dá olóòótọ́ ní ọ̀run dara pọ̀ mọ́ wọn ní sísọ pé: “Àmín! Ìbùkún àti ògo àti ọgbọ́n àti ìdúpẹ́ àti ọlá àti agbára àti okun ni fún Ọlọ́run wa títí láé àti láéláé. Àmín.”—Ìṣípayá 7:11, 12.
Jíjẹ́ Ẹni Yíyẹ
5. Báwo la ṣe lè mọ ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè wà lára ogunlọ́gọ̀ ńlá?
5 Títẹ̀lé ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Jèhófà ni yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe láti dá ogunlọ́gọ̀ ńlá sí nígbà ìpọ́njú ńlá. A to àwọn
ànímọ́ tí àwọn tí a óò dá nídè yóò ní lẹ́sẹẹsẹ sínú Bíbélì. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí àwọn tó bá fẹ́ràn òdodo gbé ìgbésẹ̀ nísinsìnyí kí wọ́n lè tóótun láti là á já. Kí làwọn wọ̀nyí gbọ́dọ̀ ṣe?6. Kí nìdí tó fi bá a mu láti fi ogunlọ́gọ̀ ńlá wé àgùntàn?
6 Àwọn àgùntàn jẹ́ ọlọ́kàntutù àti onígbọràn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tí Jésù sọ pé òun ní àwọn àgùntàn mìíràn tí kì í ṣe ẹgbẹ́ ti ọ̀run, ohun tó ní lọ́kàn ni pé wọ́n jẹ́ èèyàn tí kì í ṣe kìkì pé wọ́n fẹ́ wà láàyè títí láé nìkan ni, àmọ́ wọ́n á tún jẹ́ àwọn tí ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ rẹ̀ pẹ̀lú. Ó sọ pé: “Àwọn àgùntàn mi ń fetí sí ohùn mi, mo sì mọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé mi.” (Jòhánù 10:16, 27) Àwọn wọ̀nyí jẹ́ àwọn tí ń tẹ́tí sí ohun tí Jésù ń sọ, tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i, àní tí wọ́n di ọmọlẹ́yìn rẹ̀.
7. Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní?
7 Kí ni àwọn ànímọ́ mìíràn tó yẹ kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù wọ̀nyí ní? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáhùn pé: “Kí ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé, . . . kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfésù 4:22-24) Wọn yóò ní àwọn ànímọ́ tó ń fi kún ìṣọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àwọn ànímọ́ bí “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.”—Gálátíà 5:22, 23.
8. Kí ni ogunlọ́gọ̀ ńlá yóò dojú kọ bí wọ́n ṣe ń ṣètìlẹyìn fún àṣẹ́kù ẹni àmì òróró?
8 Ogunlọ́gọ̀ ńlá ń kọ́wọ́ ti àwọn kéréje tó ní ìrètí lílọ sí ọ̀run, ìyẹn àwọn tí ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. (Mátíù 24:14; 25:40) Àwọn àgùntàn mìíràn ń ṣe ìtìlẹyìn yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé àwọn á dojú kọ àtakò nítorí pé ìgbà tí ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ ni Kristi Jésù àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò ní ọ̀run. Èyí wá túmọ̀ sí pé, “ègbé ni fún ilẹ̀ ayé . . . nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:7-12) Abájọ tí Sátánì fi wá túbọ̀ ń fínná mọ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bí òpin ètò yìí ṣe ń sún mọ́lé.
9. Báwo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe ṣàṣeyọrí tó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà, èé sì ti ṣe?
9 Iṣẹ́ ìwàásù náà ń tẹ̀ síwájú nìṣó láìfọ̀tápè. Látorí Aísáyà 54:17) Kódà ọ̀gbẹ́ni kan lára àwọn adájọ́ ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù gbà pé iṣẹ́ Ọlọ́run kò ṣeé dá dúró. Ó bá àwọn Farisí sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Ẹ jọ̀wọ́ wọn jẹ́ẹ́; (nítorí pé, bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ ènìyàn ni ìpètepèrò tàbí iṣẹ́ yìí ti wá, a ó bì í ṣubú; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni, ẹ kì yóò lè bì wọ́n ṣubú;) bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a lè wá rí yín ní ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà ní ti gidi.”—Ìṣe 5:38, 39.
ìwọ̀nba ẹgbẹ̀rún díẹ̀ tó ń wàásù Ìjọba náà nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí, wọ́n ti di ọ̀kẹ́ àìmọye báyìí, nítorí Jèhófà ṣèlérí pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere.” (10. (a) Kí ni “àmì” iwájú orí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà túmọ̀ sí? (b) Báwo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe ń ṣègbọràn sí ‘ohùn náà láti ọ̀run’?
10 A ṣàpèjúwe àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá gẹ́gẹ́ bí àwọn tá a sàmì sí fún lílàájá. (Ìsíkíẹ́lì 9:4-6) “Àmì náà” jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, pé a ti batisí wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Jésù, àti pé wọ́n ń sapá láti ní àkópọ̀ ìwà tí Kristi ní. Wọ́n ń ṣègbọràn sí ‘ohùn náà láti ọ̀run’ tó sọ nípa ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé ti Sátánì pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.”—Ìṣípayá 18:1-5.
11. Ọ̀nà pàtàkì wo làwọn tó jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá gbà ń fi hàn pé ìránṣẹ́ Jèhófà làwọn?
11 Pẹ̀lúpẹ̀lù, Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Yàtọ̀ pátápátá sí èyí, ńṣe làwọn èèyàn tó ń ṣe àwọn ẹ̀sìn inú ayé yìí ń pa ara wọn nígbà ogun, lọ́pọ̀ ìgbà kìkì nítorí pé wọn kì í ṣọmọ ibì kan náà! Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Àwọn ọmọ Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Èṣù hàn gbangba nípasẹ̀ òtítọ́ yìí: Olúkúlùkù ẹni tí kì í bá a lọ ní ṣíṣe òdodo kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀. . . . A ní láti ní ìfẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì; kì í ṣe bí Kéènì, ẹni tí ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà, tí ó sì fikú pa arákùnrin rẹ̀.”—1 Jòhánù 3:10-12.
12. Nígbà ìpọ́njú ńlá náà, kí ni Jèhófà yóò ṣe sí “igi” tó dúró fún àwọn ẹ̀sìn tí ń so èso tí kò dára?
12 Jésù là á mọ́lẹ̀ pé: “Gbogbo igi rere a máa mú eso àtàtà jáde, ṣùgbọ́n gbogbo igi jíjẹrà a máa mú èso tí kò ní láárí jáde; igi rere kò lè so èso tí kò ní láárí, bẹ́ẹ̀ ni igi jíjẹrà kò lè mú èso àtàtà jáde. Gbogbo igi tí kì í mú èso àtàtà jáde ni a óò ké lulẹ̀, tí a ó sì sọ sínú iná. Ní ti tòótọ́, nígbà náà, nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá àwọn ènìyàn wọnnì mọ̀.” (Mátíù 7:17-20) Èso táwọn ẹ̀sìn ayé yìí ń so fi hàn pé “igi” jíjẹrà ni wọ́n, tí Jèhófà yóò pa run láìpẹ́ nígbà ìpọ́njú ńlá.—Ìṣípayá 17:16.
13. Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe fi hàn pé àwọn ń fi ìṣọ̀kan “dúró níwájú ìtẹ́” Jèhófà?
13 Ìṣípayá 7:9-15 pe àfiyèsí sí àwọn kókó tí yóò mú ká dá ogunlọ́gọ̀ ńlá náà sí. A fi hàn pé wọ́n fi ìṣọ̀kan “dúró níwájú ìtẹ́” Jèhófà, tí wọ́n ń gbé e lárugẹ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Wọ́n ti “fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” tó túmọ̀ sí pé wọ́n tẹ́wọ́ gba ẹbọ Jésù tí ń ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀. (Jòhánù 1:29) Wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, wọ́n sì fi ẹ̀rí èyí hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Fún ìdí yìí, wọ́n ní ìdúró mímọ́ níwájú Ọlọ́run, èyí tí aṣọ funfun tí wọ́n wọ̀ ṣàpẹẹrẹ rẹ̀, “wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un tọ̀sán-tòru.” Ǹjẹ́ àwọn ọ̀nà kan wà tó o lè gbà mú kí ìgbésí ayé rẹ túbọ̀ bá ohun tá a sọ níhìn-ín mu?
Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nísinsìnyí
14. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń gbádùn nísinsìnyí pàápàá?
14 Ó ṣeé ṣe kó o ti ṣàkíyèsí àwọn àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ tí àwọn tó ń sin Jèhófà ń gbádùn nísinsìnyí pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà tó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ète òdodo Jèhófà lo wá rí i pé ìrètí tí ń mọ́kàn yọ̀ ń bẹ fún ọ lọ́jọ́ iwájú. Ìwọ náà wá ní ète gúnmọ́ nínú ìgbésí ayé—ìyẹn láti sin Ọlọ́run tòótọ́ náà pẹ̀lú ìrètí aláyọ̀ ti ìyè ayérayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Àní sẹ́, Jésù Kristi Ọba yóò “ṣamọ̀nà [ogunlọ́gọ̀ ńlá] lọ sí àwọn ìsun omi ìyè.”—Ìṣípayá 7:17.
15. Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń jàǹfààní nínú rírọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì lórí ọ̀ràn òṣèlú àti ìwà rere?
15 Àǹfààní àgbàyanu tí ogunlọ́gọ̀ ńlá ń gbádùn ni ìfẹ́, àjọṣepọ̀ àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kárí ayé. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé oúnjẹ tẹ̀mí kan náà ni gbogbo wa jọ ń jẹ, gbogbo wa ló ń ṣègbọràn sí àwọn òfin àti ìlànà kan náà tí ń bẹ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí ọ̀ràn òṣèlú tàbí ti orílẹ̀-èdè kò fi lè pín wa níyà. Bákan náà, à ń tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere gíga tí Ọlọ́run là sílẹ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé dípò gbọ́nmi-si omi-ò-to, ìyapa àti ìṣekúṣe tó gbòde kan láyé, àwọn èèyàn Jèhófà ń gbádùn ohun tá a lè pè ní Párádísè tẹ̀mí. Kíyè sí bí Aísáyà 65:13, 14 ṣe ṣàpèjúwe èyí.
16. Láìka àwọn ìṣòro tó wọ́pọ̀ láyé yìí sí, ìrètí wo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá ní?
16 Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ìṣípayá 21:4.
Jèhófà ti di pípé o. Àwọn ìṣòro tó ń fìtínà ọ̀pọ̀ èèyàn láyé yìí kan àwọn náà, àwọn ìṣòro bí àìríjẹ-àìrímu tàbí wíwà lára àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ tí ogun àwọn orílẹ̀-èdè ń ṣàkóbá fún. Wọ́n tún ń dojú kọ àìsàn, ìyà, àti ikú. Ṣùgbọ́n wọ́n ní ìgbàgbọ́ pé nínú ayé tuntun, Ọlọ́run yóò “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—17. Láìka ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí wa nísinsìnyí sí, ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu wo ní ń bẹ níwájú fáwọn tó bá ń sin Ọlọ́run tòótọ́?
17 Kódà bó o bá pàdánù ẹ̀mí rẹ nísinsìnyí nítorí ọjọ́ ogbó, àìsàn, jàǹbá, tàbí inúnibíni, Jèhófà yóò jí ọ dìde sí ìyè nínú Párádísè. (Ìṣe 24:15) Nígbà náà, wàá máa bá a lọ ní gbígbádùn àsè tẹ̀mí nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run yóò jinlẹ̀ sí i bó ṣe ń rí i pé àwọn ète rẹ̀ ń ní ìmúṣẹ ológo. Àwọn ìbùkún ti ara tí Jèhófà yóò pèsè nígbà yẹn yóò jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní fún un túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. (Aísáyà 25:6-9) Ẹ ò rí i pé ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu ń bẹ níwájú fáwọn èèyàn Ọlọ́run!
Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò
• Ìṣẹ̀lẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ wo ni Bíbélì so pọ̀ mọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá náà?
• Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la fẹ́ wà lára ogunlọ́gọ̀ ńlá náà tó rí ojú rere Ọlọ́run, kí la gbọ́dọ̀ ṣe nísinsìnyí?
• Báwo làwọn ìbùkún tí ogunlọ́gọ̀ ńlá ń gbádùn nísinsìnyí àtàwọn èyí tí wọ́n máa gbádùn nínú ayé tuntun Ọlọ́run ṣe ṣe pàtàkì sí ọ tó?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 123]
Ọ̀kẹ́ àìmọye ogunlọ́gọ̀ ńlá ń fi ìṣọ̀kan jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́