Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Bí Ọlọ́run Ṣe Fàyè Gba Ìwà Ibi
Orí Keje
Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Bí Ọlọ́run Ṣe Fàyè Gba Ìwà Ibi
1, 2. (a) Ká ní Jèhófà ti pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà run lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní Édẹ́nì, báwo ni ìyẹn ì bá ti nípa lórí wa? (b) Àwọn ìpèsè onífẹ̀ẹ́ wo ni Jèhófà ti ṣe fún wa?
BÀBÁ ńlá náà, Jékọ́bù, sọ pé: “Ọjọ́ ọdún ìgbésí ayé mi kéré níye, ó sì kún fún wàhálà.” (Jẹ́nẹ́sísì 47:9) Bákan náà, Jóòbù sọ pé “ọlọ́jọ́ kúkúrú ni” ènìyàn “ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.” (Jóòbù 14:1) Bíi tiwọn, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wa ló ti fojú winá ìṣòro, àìsí ìdájọ́ òdodo àtàwọn ọ̀ràn tí ń kó ìbànújẹ́ báni pàápàá. Síbẹ̀, bíbí tí Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n bí wa kò túmọ̀ sí pé ó ṣe ohun tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu. Lóòótọ́, a ò ní èrò inú àti ara pípé bíi ti Ádámù àti Éfà, bẹ́ẹ̀ la ò sì gbé nínú Párádísè bíi tiwọn. Àmọ́ báwo ni ì bá ti rí ká ní Jèhófà ti pa wọ́n run lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀? Òótọ́ ni pé àìsàn, ìbànújẹ́ tàbí ikú kò ní sí, àmọ́, ìran èèyàn pàápàá ò ní sí lónìí pẹ̀lú. Wọn ò tiẹ̀ ní bí wa rárá ni. Ṣùgbọ́n nínú àánú rẹ̀, Ọlọ́run gba Ádámù àti Éfà láyè láti bí àwọn ọmọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ wọ̀nyí jogún àìpé. Nípasẹ̀ Kristi, Jèhófà tiẹ̀ tún bá wa ṣètò bí a ṣe lè rí ohun tí Ádámù gbé sọ nù gbà padà, ìyẹn ìyè ayérayé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 10:10; Róòmù 5:12.
2 Ó mà ń múni lọ́kàn yọ̀ o, pé a lè máa fojú sọ́nà de gbígbé títí láé nínú ayé tuntun tó ti di Párádísè! Ibẹ̀ la ti máa bọ́ lọ́wọ́ àìsàn, ìbànújẹ́, ìrora àti ikú, àti Òwe 2:21, 22; Ìṣípayá 21:4, 5) Àmọ́, níbàámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Bíbélì, a mọ̀ pé bí ìgbàlà wa tiẹ̀ ṣe pàtàkì sí wa gan-an àti sí Jèhófà, ohun kan wà tó ṣe kókó jùyẹn lọ tó so mọ́ ọ̀ràn yìí.
lọ́wọ́ àwọn èèyàn búburú pàápàá. (Nítorí Orúkọ Ńlá Rẹ̀
3. Kí lóhun náà tó so mọ́ mímú ète Jèhófà fún ilẹ̀ ayé àti aráyé ṣẹ?
3 Orúkọ Ọlọ́run ní í ṣe pẹ̀lú mímú ète rẹ̀ fún ilẹ̀ ayé àti aráyé ṣẹ. Orúkọ yẹn, Jèhófà, túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Nítorí náà, orúkọ rẹ̀ wé mọ́ irú ẹni tó jẹ́, pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run, Awíbẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀ àti Ọlọ́run òtítọ́. Nítorí ipò tí Jèhófà dì mú, bí gbogbo àwọn tó wà láyé àti lọ́run bá máa wà ní àlàáfíà láìsí ìṣòro, ó ń béèrè pé kí wọ́n bu ọ̀wọ̀ kíkún tó sì yẹ fún orúkọ rẹ̀ àti ohun tó dúró fún, kí gbogbo wọn sì máa ṣègbọràn sí i.
4. Kí ni ète Jèhófà fún ilẹ̀ ayé ní nínú?
4 Lẹ́yìn tí Jèhófà dá Ádámù àti Éfà tán, ó fún wọn níṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe. Ó jẹ́ kó yé wọn pé ète òun kì í ṣe pé kí wọ́n ṣèkáwọ́ ilẹ̀ ayé nìkan, èyí tó túmọ̀ sí pé wọ́n á mú ààlà Párádísè fẹ̀ sí i, àmọ́ pé kí wọ́n fi àtọmọdọ́mọ wọn kúnnú rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ṣé ète yìí kò wá ní ṣẹ nítorí ẹ̀ṣẹ́ tí wọ́n dá ni? Ẹ̀gàn pátápátá gbáà nìyẹn á mà mú wá sórí orúkọ Jèhófà Olódùmarè, tí kò bá lè mú ète tó ní fún ilẹ̀ ayé àti àwọn èèyàn inú rẹ̀ ṣẹ!
5. (a) Bí àwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ bá jẹ nínú igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìgbà wo ni wọ́n máa kú? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó sọ nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:17 ṣẹ tí kò sì tún yí ète tó ní fún ilẹ̀ ayé padà?
5 Jèhófà ti kìlọ̀ fún Ádámù àti Éfà pé bí wọ́n bá ṣàìgbọràn tí wọ́n sì jẹ lára igi ìmọ̀ rere àti búburú, Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Ohun tí Jèhófà sọ gẹ́lẹ́ ló ṣẹ, ọjọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ gan-an ló pè wọ́n láti wá dáhùn fún ohun tí wọ́n ṣe ó sì dájọ́ ikú fún wọn. Lójú Ọlọ́run, ọjọ́ yẹn gan-an ni Ádámù àti Éfà kú. Àmọ́ láti lè rí i pé ète tó ní fún ilẹ̀ ayé ní ìmúṣẹ, Jèhófà gbà wọ́n láyè láti bímọ kí wọ́n tó kú nípa ti ara. Síbẹ̀, níwọ̀n bó ti ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti wo ẹgbẹ̀rún ọdún bí ọjọ́ kan, nígbà tí ìwàláàyè Ádámù dópin lẹ́ni ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n [930], àárín “ọjọ́” kan ló ṣì jẹ́. (2 Pétérù 3:8; Jẹ́nẹ́sísì 5:3-5) Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà fi hàn pé òún jẹ́ olóòótọ́ nípa ìgbà tí òun yóò mú ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn wá sórí wọn, síbẹ̀ ikú wọn kò ba ète rẹ̀ fún ilẹ̀ ayé jẹ́. Àmọ́ fún àkókò kan, ó ń yọ̀ǹda fún àwọn èèyàn aláìpé, títí kan àwọn ẹni ibi pẹ̀lú, láti wà láàyè.
“ọjọ́” tí wọ́n bá jẹ ẹ́ ni wọ́n máa kú. (6, 7. (a) Níbàámu pẹ̀lú Ẹ́kísódù 9:15, 16, èé ṣe tí Jèhófà fi fàyè gba ìwà búburú láti máa bá a lọ fún àkókò kan? (b) Nínú ọ̀ràn ti Fáráò, báwo ni a ṣe fi agbára Jèhófà hàn, báwo sì ni a ṣe sọ orúkọ Rẹ̀ di mímọ̀? (d) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà ti ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí bá wá sópin?
6 Ohun tí Jèhófà sọ fún alákòóso ilẹ̀ Íjíbítì nígbà ayé Mósè jẹ́ ká túbọ̀ rí ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi láti máa bá a lọ. Nígbà tí Fáráò kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, Jèhófà kò pa á run lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó mú ìyọnu mẹ́wàá wá sórí ilẹ̀ náà, èyí tó fi agbára rẹ̀ hàn lọ́nà àgbàyanu. Nígbà tí Jèhófà ń sọ nípa ìyọnu keje tóùn ń mú bọ̀, ó sọ fún Fáráò pé lọ́gán ni Òun ì bá ti pa Fáráò àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀. Jèhófà wá sọ pé: “Ṣùgbọ́n, ní ti tòótọ́, fún ìdí yìí ni mo ṣe mú kí o máa wà nìṣó, nítorí àtifi agbára mi hàn ọ́ àti nítorí kí a lè Ẹ́kísódù 9:15, 16.
polongo orúkọ mi ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”—7 Lóòótọ́, nígbà tí Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè, orúkọ rẹ̀ di èyí tí gbogbo ayé mọ̀. (Jóṣúà 2:1, 9-11) Lónìí, tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àtààbọ̀ [3,500] ọdún lẹ́yìn ìgbà náà, ohun tó ṣe nígbà yẹn kò tíì dìgbàgbé. Kì í ṣe pé orúkọ náà, Jèhófà, di èyí tá a kéde rẹ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n òtítọ́ nípa Ẹni tó ń jẹ́ orúkọ yẹn tún di mímọ̀ pẹ̀lú. Èyí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó máa ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ tó sì máa ń gbégbèésẹ̀ tó yẹ nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (Jóṣúà 23:14) Èyí fi hàn kedere pé, nítorí agbára ńlá tó ní, kò sóhun náà tó lè dí ète rẹ̀ lọ́wọ́ kó má ṣẹ. (Aísáyà 14:24, 27) Nítorí náà, a lè fọkàn balẹ̀ pé yóò tìtorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ gbégbèésẹ̀ láìpẹ́ nípa pípa gbogbo ètò búburú Sátánì run. Agbára ńlá tí Jèhófà máa lò yìí àti ògo tó máa mú bá orúkọ Rẹ̀ kò ní dìgbàgbé láé. Àwọn àǹfààní rẹ̀ kò sì ní dópin.—Ìsíkíẹ́lì 38:23; Ìṣípayá 19:1, 2.
‘Ọgbọ́n Ọlọ́run Mà Jinlẹ̀ O’
8. Àwọn kókó wo ni Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká gbé yẹ̀ wò?
8 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù, ó béèrè ìbéèrè kan pé: “Àìṣèdájọ́ òdodo ha wà pẹ̀lú Ọlọ́run bí?” Ó fi taratara dáhùn pé: “Kí èyíinì má ṣe rí bẹ́ẹ̀ láé!” Ẹ̀yìn náà ló wá tẹnu mọ́ àánú Ọlọ́run ó sì tọ́ka sí ohun tí Jèhófà sọ nípa ìdí tó fi gba Fáráò láyè láti máa wà láàyè nìṣó fún sáà kan. Pọ́ọ̀lù tún fi hàn pé bí amọ̀ lọ́wọ́ amọ̀kòkò làwa èèyàn rí. Ó wá sọ pé: “Wàyí o, bí Ọlọ́run, bí ó tilẹ̀ ní ìfẹ́ láti fi ìrunú rẹ̀ hàn gbangba, kí ó sì sọ agbára rẹ̀ di mímọ̀, Róòmù 9:14-24.
bá fi ọ̀pọ̀ ìpamọ́ra fàyè gba àwọn ohun èlò ìrunú tí a mú yẹ fún ìparun, kí ó bàa lè sọ àwọn ọrọ̀ ògo rẹ̀ di mímọ̀ lórí àwọn ohun èlò àánú, èyí tí ó pèsè sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ fún ògo, èyíinì ni, àwa, tí ó pè kì í ṣe láti àárín àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, ìyẹn ńkọ́?”—9. (a) Àwọn wo ni “ohun èlò ìrunú tí a mú yẹ fún ìparun”? (b) Pẹ̀lú gbogbo ohun tí àwọn alátakò rẹ̀ ń ṣe, kí nìdí tí Jèhófà fi fi ìpamọ́ra tó ga hàn, báwo sì ni àbájáde ìkẹyìn yóò ṣe já sí ire àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀?
9 Látìgbà ìṣọ̀tẹ̀ ní Édẹ́nì, ẹnikẹ́ni tó bá ti ta ko Jèhófà àti àwọn òfin rẹ̀ ti di “ohun èlò ìrunú tí a mú yẹ fún ìparun.” Àtìgbà náà wá ni Jèhófà ti ń lo ìpamọ́ra. Àwọn ẹni ibi ti fi ọ̀nà tó ń gbà ṣe nǹkan ṣẹ̀sín, wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, wọ́n tilẹ̀ tún pa Ọmọ rẹ̀ pàápàá. Nípa lílo ìkóra-ẹni-níjàánu tó ga, Jèhófà ti fi àkókò tí ó tó sílẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá láti fojú ara wọn rí àwọn àbájáde búburú tó wá látinú ṣíṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run àti ìṣàkóso èèyàn láìsí ọwọ́ Ọlọ́run níbẹ̀. Síbẹ̀, ikú Jésù ti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún dídá aráyé onígbọràn nídè àti ‘fífọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.’—1 Jòhánù 3:8; Hébérù 2:14, 15.
10. Èé ṣe tí Jèhófà fi fàyè gba àwọn ẹni búburú láti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá [1,900] ọdún sẹ́yìn?
10 Fún ohun tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá [1,900] ọdún látìgbà àjíǹde Jésù, Jèhófà ṣì ń bá a nìṣó láti gba “àwọn ohun èèlò ìrunú” láyè, kò tíì pa wọ́n run. Fún ìdí wo? Ìdí kan jẹ́ nítorí pé ó ń múra àwọn tí yóò wà pẹ̀lú Jésù Kristi nínú Ìjọba rẹ̀ ọ̀run sílẹ̀. Iye àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, àwọn sì ni “ohun èèlò àánú” tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ rẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, Lúùkù 22:29; Ìṣípayá 14:1-4.
a ké sí àwọn èèyàn láàárín àwọn Júù láti wá di ẹgbẹ́ ti ọ̀run yìí. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run ké sí àwọn èèyàn látinú àwọn orílẹ̀-èdè Kèfèrí. Kò sí ọ̀kankan nínú àwọn wọ̀nyí tí Jèhófà fipá mú láti wá sin òun. Àmọ́ láàárín àwọn tó fi ìmọrírì hàn fún àwọn ìṣètò onífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó fún àwọn díẹ̀ ní àǹfààní oníyebíye náà láti jẹ́ alákòóso pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ nínú Ìjọba ọ̀run. Mímúra àwọn ẹgbẹ́ ti ọ̀run yẹn sílẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí báyìí.—11. (a) Ẹgbẹ́ wo ló ń jàǹfààní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí látinú ìpamọ́ra Jèhófà? (b) Báwo làwọn tó ti kú yóò ṣe jàǹfààní?
11 Àmọ́ báwo ni ti rírí àwọn èèyàn tó máa gbénú ayé? Ìpamọ́ra Jèhófà ti mú kó ṣeé ṣe bákan náà láti kó “ogunlọ́gọ̀ ńlá” jọ láti inú gbogbo orílẹ̀ èdè. Wọn ti di ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù báyìí. Jèhófà ti ṣèlérí pé ẹgbẹ́ ti ilẹ̀ ayé yìí yóò la òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí já wọn yóò sì ní ìrètí gbígbé títí láé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 7:9, 10; Sáàmù 37:29; Jòhánù 10:16) Ní àsìkò tó tọ́ lójú Ọlọ́run, a óò jí ọ̀pọ̀ jaburata àwọn òkú dìde a óò sì fún wọn ní àǹfààní láti jẹ́ ọmọ-abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ nínú Ìṣe 24:15 pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Jòhánù 5:28, 29.
12. (a) Kí la kọ́ nípa Jèhófà látinú bó ṣe fara da ìwà ibi? (b) Kí lèrò rẹ nípa ọ̀nà tí Jèhófà gbà yanjú àwọn ọ̀ràn yìí?
12 Ǹjẹ́ àìṣèdájọ́ òdodo kankan wà nínú gbogbo èyí? Rárá o, nítorí pé, bí Ọlọ́run kò ṣe tíì pa àwọn ẹni búburú tàbí “àwọn ohun èèlò ìbínú” run, ńṣe ló ń fi ìyọ́nú hàn sí àwọn mìíràn ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀. Èyí ń fi bó ṣe jẹ́ aláàánú àti onífẹ̀ẹ́ tó hàn. Bákan náà, pẹ̀lú bí a ṣe ní àkókò tó láti kíyè sí bí àwọn ète rẹ̀ Róòmù 11:33.
ṣe ń nímùúṣẹ, ohun púpọ̀ la ti kọ́ nípa Jèhófà fúnra rẹ̀. Ìdájọ́ òdodo, àánú, ìpamọ́ra àti ọgbọ́n tó ń fi hàn lóríṣiríṣi ọ̀nà ń yà wá lẹ́nu. Ọgbọ́n tí Jèhófà fi yanjú ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run, ìyẹn ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti ṣàkóso—yóò máa wà bí ẹ̀rí títí láé pé kò sí ọ̀nà ìṣàkóso mìíràn tó lè dà bíi tirẹ̀. Àwa náà gbà pẹ̀lú ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámárìídìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!”—Àǹfààní Tá A Ní Láti Fi Ìfọkànsìn Wa Hàn
13. Nígbà tí a bá wà nínú ìṣòro, àǹfààní wo ló ṣí sílẹ̀ fún wa, kí ló sì máa jẹ́ ká lè hùwà ọlọgbọ́n?
13 Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló wà nínú ìṣòro. Ìṣòro wọn sì ń bá a nìṣó nítorí pé Ọlọ́run kò tíì pa àwọn ẹni ibi run kó sì mú aráyé bọ̀ sípò gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Ṣé ńṣe ló yẹ ká jẹ́ kí èyí bà wá lọ́kàn jẹ́? Ǹjẹ́ kì í ṣe pé ńṣe ló yẹ ká wo irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ bí àǹfààní tá a ní láti kópa nínú fífi Èṣù hàn ní òpùrọ́? A lè rí okun láti ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá fi àrọwà náà sọ́kàn èyí tó sọ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” (Òwe 27:11) Sátánì, ẹni tó ń ṣáátá Jèhófà kò jáwọ́ nínú sísọ pé tí àwọn èèyàn bá pàdánù àwọn ohun ìní ti ara tàbí tí àìsàn bá kọ lù wọ́n, wọ́n yóò dá Ọlọ́run lẹ́bi, wọ́n á tilẹ̀ bú u pàápàá. (Jóòbù 1:9-11; 2:4, 5) À ń mú ọkàn Jèhófà yọ̀ nígbà tí a bá dúró ṣinṣin tì í lójú ìṣòro tí a sì ń fi hàn pé, ní tiwa o, ọ̀rọ̀ kò rí bí Sátánì ṣe sọ.
14. Tá a bá gbára lé Jèhófà nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro, àwọn àǹfààní wo ló lè mú wá fún wa?
14 Tá a bá gbára lé Jèhófà nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro, èyí á lè mú ká ní àwọn ànímọ́ tó ṣeyebíye. Bí àpẹẹrẹ, Hébérù 5:8, 9; 12:11; Jákọ́bù 1:2-4.
nítorí ìyà tí Jésù jẹ, ó “kọ́ ìgbọràn” lọ́nà tí kò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Àwa náà lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ìṣòro wa, nípa pé a lè kọ́ láti ní ìpamọ́ra, ìfaradà àti ìmọrírì jíjinlẹ̀ tá a gbé ka òye tá a ní nípa àwọn ọ̀nà òdodo Jèhófà.—15. Báwo ni àwọn mìíràn á ṣe jàǹfààní tá a bá fara da ìṣòro?
15 Àwọn ẹlòmíràn yóò kíyè sí bí a ti ń ṣe. Nítorí ohun tá a fara dà nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ òdodo, bí àkókò ti ń lọ, díẹ̀ lára àwọn èèyàn tí ń wò wá lè wá dá àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́ lónìí mọ̀. Bí wọ́n bá sì dara pọ̀ mọ́ wa nínú ìjọsìn, àwọn náà lè di ẹni tó máa gba ìbùkún Mátíù 25:34-36, 40, 46) Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ fẹ́ kí àwọn èèyàn ní àǹfààní yẹn.
ìyè àìnípẹ̀kun. (16. Báwo ni ojú tá a fi ń wo ìṣòro tá a ní ṣe kan ọ̀ràn ìṣọ̀kan?
16 Ohun tó dára mà ni o, tá a bá ń wo àwọn ipò tó ṣòro pàápàá bí àǹfààní láti fi ìfọkànsìn wa sí Jèhófà hàn àti ọ̀nà láti kópa nínú mímú kí ìfẹ́ rẹ̀ yọrí sí rere! Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wa lè jẹ́ ẹ̀rí pé lóòótọ́ là ń gbìyànjú láti wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run àti Kristi. Jésù gbàdúrà sí Jèhófà nítorí gbogbo àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́, ó sọ pé: “Èmi kò ṣe ìbéèrè nípa àwọn wọ̀nyí nìkan [àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà pẹ̀lú rẹ̀], ṣùgbọ́n nípa àwọn tí yóò ní ìgbàgbọ́ nínú mi pẹ̀lú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn; kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, tí èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí àwọn náà lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wa.”—Jòhánù 17:20, 21.
17. Ìdánilójú wo la lè ní bí a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà?
17 Bí a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, yóò san èrè jaburata fún wa. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ẹ di aláìṣeéṣínípò, kí ẹ máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa, ní mímọ̀ pé òpò yín kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 15:58) Ó tún sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.” (Hébérù 6:10) Jákọ́bù 5:11 sọ pé: “Wò ó! Àwọn tí wọ́n lo ìfaradà ni à ń pè ní aláyọ̀. Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ìyọrísí tí Jèhófà mú wá, pé Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.” Kí ló jẹ́ àbájáde rẹ̀ fún Jóòbù? “Ní ti Jèhófà, ó bù kún ìgbẹ̀yìn Jóòbù ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ.” (Jóòbù 42:10-16) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ni “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Ẹ sì wo irú èrè tá à ń wọ̀nà fún—ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè ilẹ̀ ayé!
18. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìrántí bíbanilọ́kànjẹ́ èyíkéyìí tá a lè ní?
18 Ìjọba Ọlọ́run yóò mú gbogbo àdánù tó ti bá ìdílé ẹ̀dá èèyàn fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tó ti kọjá kúrò. Ìdùnnú tó máa wà nígbà yẹn á ju ìṣòro èyíkéyìí tó ń bá wa fínra nísinsìnyí lọ fíìfíì. Àwọn ohun burúkú tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn kò ní wá sí wa lọ́kàn mọ́. Àwọn ìrònú tí ń gbéni ró, àtàwọn ìgbòkègbodò tí yóò wà fún gbogbo èèyàn nínú ayé tuntun yẹn láti ṣe yóò máa mú àwọn ìrántí tó ń bani nínú jẹ́ náà kúrò díẹ̀díẹ̀. Jèhófà polongo pé: “Èmi yóò dá ọ̀run tuntun [Ìjọba ọ̀run tuntun kan tí yóò máa ṣàkóso lórí aráyé] àti ilẹ̀ ayé tuntun [ẹgbẹ́ ìràn èèyàn olódodo kan]; àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà. Ṣùgbọ́n ẹ yọ ayọ̀ ńláǹlà, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá.” Ní tòótọ́, nínú ayé tuntun ti Jèhófà, àwọn olódodo yóò lè sọ pé: “Gbogbo ilẹ̀ ayé ti sinmi, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu. Àwọn ènìyàn ti tújú ká pẹ̀lú igbe ìdùnnú.”—Aísáyà 14:7; 65:17, 18.
Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò
• Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà fàyè gba ìwà ibi, ọ̀nà wo ló ti gbà fi ọ̀wọ̀ tó tọ́ hàn sí orúkọ tirẹ̀ fúnra rẹ̀?
• Báwo ni fífaradà tí Ọlọ́run fara da “àwọn ohun èèlò ìrunú” ṣe jẹ́ kí àánú rẹ̀ nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ wa?
• Kí ló yẹ ká gbìyànjú láti rí nínú àwọn ipò ìṣòro tó lè máa bá wa fínra?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 67]
Jèhófà “bù kún ìgbẹ̀yìn Jóòbù ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ”