Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Wíwọ̀yá Ìjà Pẹ̀lú Agbo Ọmọ Ogun Ẹ̀mí Búburú’

‘Wíwọ̀yá Ìjà Pẹ̀lú Agbo Ọmọ Ogun Ẹ̀mí Búburú’

Orí Kẹjọ

Wíwọ̀yá Ìjà Pẹ̀lú Agbo Ọmọ Ogun Ẹ̀mí Búburú

1. Kí ló mú kí á pe àfiyèsí wa sí ìgbòkègbodò àwọn ẹ̀mí búburú?

ŃṢE làwọn kan máa ń ṣe yẹ̀yẹ́ bí wọ́n bá gbọ́ pé àwọn ẹ̀mí búburú wà. Àmọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ yẹ̀yẹ́ o. Yálà àwọn èèyàn gbà tàbí wọn ò gbà, àwọn ẹ̀mí búburú ńbẹ, kò sì sẹ́nì kan tí wọn kì í gbìyànjú láti yọ lẹ́nu. Kódà, wọ́n ń yọ àwọn olùjọsìn Jèhófà náà lẹ́nu. Àní, àwọn gan-an ni wọ́n dájú sọ jù lọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe àfiyèsí wa sí òtítọ́ yìí, ó sọ pé: “Àwa ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe lòdì sí àwọn alákòóso [tí a kò lè fojú rí], lòdì sí àwọn aláṣẹ, lòdì sí àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” (Éfésù 6:12) Wàhálà táwọn ọmọ ogun ẹ̀mí búburú ń dá sílẹ̀ lọ́jọ́ wa ju ti ìgbàkígbà rí lọ nítorí a ti lé Sátánì kúrò ní ọ̀run inú sì ń bí i gidigidi, ní mímọ̀ pé àkókò kúkúrú ló kù fún òun.—Ìṣípayá 12:12.

2. Báwo la ṣe lè ṣẹ́gun nínú ìjàkadì tí à ń bá àwọn ẹ̀mí tí wọ́n lágbára ju èèyàn lọ jà?

2 Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé ṣe láti ṣẹ́gun nínú ìjàkadì tí à ń bá àwọn ọmọ ogún ẹ̀mí tí wọ́n lágbára ju èèyàn lọ jà? Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n kìkì nípa gbígbára lé Jèhófà pátápátá ni. A gbọ́dọ̀ tẹ́tí sí i ká sì ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a ó lè yẹra fún ọ̀pọ̀ jàǹbá, ti ara, ti ìwà rere, àti ti ìrònú, tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó wà lábẹ́ ìdarí Sátánì.—Jákọ́bù 4:7.

Àwọn Alákòóso Ayé Tí Kò Ṣeé Fojú Rí

3. Àwọn wo ni Sátánì gbéjà kò lọ́nà rírorò, ọ̀nà wo ló sì ń gbà ṣe é?

3 Jèhófà ṣàpèjúwe bí ipò ayé ṣe rí fún wa ní kedere, bó ti ń wò ó láti ipò rẹ̀ gíga ní ọ̀run. Ó fún àpọ́sítélì Jòhánù ní ìran kan, níbi tá a ti ṣàpèjúwe Sátánì bíi “dírágónì ńlá aláwọ̀ iná.” Ká ló ṣeé ṣe ni, ó múra tán láti ba Ìjọba Mèsáyà ti Ọlọ́run jẹ́ ráúráú ní gbàrà tó bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso ní ọ̀run ní 1914. Nígbà tí Sátánì kò rí ìyẹn ṣe, ló bá gbé inúnibíni gbígbóná janjan dìde sáwọn aṣojú Ìjọba yẹn tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 12:3, 4, 13, 17) Báwo ni Sátánì ṣe ń jagun yìí? Àwọn aṣojú rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé ló ń lò.

4. Ta ni orísun agbára ìjọba èèyàn, báwo la sì ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?

4 Lẹ́yìn ìyẹn la tún fi ẹranko ẹhànnà kan tó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá han Jòhánù, ẹranko náà ní àṣẹ “lórí gbogbo ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n àti orílẹ̀-èdè.” Ẹranko yẹn dúró fún gbogbo ètò ìṣèlú ayé látòkèdélẹ̀. A sọ fún Jòhánù pé “Dírágónì náà [Sátánì Èṣù] sì fún ẹranko náà ní agbára rẹ̀ àti ìtẹ́ rẹ̀ àti ọlá àṣẹ ńlá.” (Ìṣípayá 13:1, 2, 7) Bẹ́ẹ̀ ni o, Sátánì ni orísun tí àwọn ìjọba ènìyàn ti ń gba agbára àti àṣẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe kọ ọ́ sílẹ̀, àwọn tó ń “ṣàkóso ayé” lóòótọ́ ni “àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run,” tí wọ́n ń darí ìjọba ènìyàn. Gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ láti jọ́sìn Jèhófà ló gbọ́dọ̀ mọ bí kókó yìí ṣe ṣe pàtàkì tó.—Lúùkù 4:5, 6.

5. Kí làwọn alákòóso òṣèlú ń gbára jọ pọ̀ fún nísinsìnyí?

5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ alákòóso òṣèlú máa ń sọ pé àwọn ń jọ́sìn Ọlọ́run, kò sí ọ̀kankan nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó fara rẹ̀ sábẹ́ ìṣàkóso Jèhófà tàbí sábẹ́ ìṣàkóso Jésù Kristi, Ọba rẹ̀ tó yàn. Gbogbo wọn ló ń ja ìjà àjàkú-akátá láti rí i pé agbára kò bọ́ lọ́wọ́ àwọn. Lónìí, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ inú Ìṣípayá ṣe fi hàn, “àwọn àgbéjáde tí àwọn ẹ̀mí èṣù mí sí” ń kó àwọn alákòóso ayé jọ pọ̀ sí “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” ní Amágẹ́dọ́nì.—Ìṣípayá 16:13, 14, 16; 19:17-19.

6. Èé ṣe tó fi yẹ ká ṣọ́ra ká má bàa di ẹni tí a tàn jẹ láti máa ti ètò Sátánì lẹ́yìn?

6 Lójoojúmọ́, wàhálà ọ̀ràn ìṣèlú, ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ti ètò ìṣúnná owó àti ti ìsìn ń nípa lórí ìgbésí ayé àwọn èèyàn lọ́nà tí ń pín wọn yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Nínú àwọn rògbòdìyàn wọ̀nyí, kò ṣàì wọ́pọ̀ káwọn èèyàn máa sọ pé orílẹ̀-èdè kan, ẹ̀yà kan, àwọn tí ń sọ èdè kan tàbí ẹgbẹ́ kan láwùjọ àwọn làwọ́n fara mọ́—bóyá nínú ọ̀rọ̀ wọn tàbí nínú ìṣesí wọn. Kódà, nígbà táwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ kópa ní tààràtà nínú rògbòdìyàn kan, wọ́n sábàá máa ń rí i pé àwọ́n nífẹ̀ẹ́ apá kan ju apá kejì lọ. Àmọ́ láìka ẹni yòówù tàbí àjọ èyíkéyìí tí wọ́n lè sọ pé àwọ́n fara mọ́ sí, ta lẹni náà gan-an tí wọ́n ń tì lẹ́yìn? Bíbélì sọ ojú abẹ níkòó pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Nígbà náà, báwo ni ẹnì kan ṣe lè yẹra fún dídi ẹni tí a ṣì lọ́nà pa pọ̀ mọ́ ìyókù aráyé? Kìkì nípa títi Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn láìkù síbì kan ni, kí ó sì máa bá a lọ láìdá sí tọ̀tún-tòsì nínú àwọn rògbòdìyàn ayé.—Jòhánù 17:15, 16.

Àwọn Ọ̀nà Ọgbọ́n Ẹ̀wẹ́ Tí Ẹni Búburú Náà Ń Lò

7. Báwo ni ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí Sátánì ṣe fara hàn nínú lílò tó ń lo ìsìn èké?

7 Jálẹ̀ ìtàn, Sátánì ti lo inúnibíni láti fi mú kí àwọn èèyàn fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀, ó lè jẹ́ nípa ọ̀rọ̀ kòbákùngbé, ìfiniṣeyẹ̀yẹ́ tàbí ìwà ìkà. Ó tún lo àwọn ọ̀nà àrékérekè mìíràn pẹ̀lú, ìyẹn àwọn ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí àti ọgbọ́n ẹ̀wẹ́. Ó tún fọgbọ́n lo ìsìn èké láti fi sọ àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ di aláìmọ̀kan, ó mú kí wọ́n máa ronú pé Ọlọ́run làwọ́n ń sìn. Nítorí pé wọn ò ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run tí wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, àwọn ààtò ẹ̀sìn ìmùlẹ̀ àti ìsọjí onítara lè máa fà wọ́n mọ́ra tàbí kí iṣẹ́ ìyanu máa wú wọn lórí. (2 Tẹsalóníkà 2:9, 10) Àmọ́ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé, kódà láàárín àwọn tó ti ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ tẹ́lẹ̀ “àwọn kan yóò yẹsẹ̀ . . . , ní fífi àfiyèsí sí àwọn àsọjáde onímìísí tí ń ṣini lọ́nà àti àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù.” (1 Tímótì 4:1) Ọ̀nà wo nìyẹn lè gbà ṣẹlẹ̀?

8. Ọ̀nà wo ni Sátánì lè gbà fà wá sínú ìsìn èké kódà ká tiẹ̀ ní à ń jọ́sìn Jèhófà?

8 Èṣù máa ń tibi àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa mú wa nípa lílo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí. Ṣé ìbẹ̀rù èèyàn ṣì máa ń kó wa láyà jẹ? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a lè torí pé àwọn mọ̀lẹ́bí tàbí àwọn aládùúgbò ń dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ wa, ká lọ lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà tó tinú ìsìn èké wá. Ṣé a máa ń gbéra ga? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè fárígá nígbà tí wọ́n bá fún wa nímọ̀ràn tàbí nígbà táwọn ẹlòmíràn kò bá tẹ́wọ́ gba èrò wa. (Òwe 15:10; 29:25; 1 Tímótì 6:3, 4) Dípò ká tún ìrònú wa ṣe kó lè bá àpẹẹrẹ Kristi mu, a lè máa nífẹ̀ẹ́ sí àwọn táá máa ‘rin wá létí,’ tí wọ́n á máa sọ pé tá a bá ṣáà ti ń ka Bíbélì tá ò sì ṣe ohun tó burú, ìyẹn náà ti tó. (2 Tímótì 4:3) Yálà a lọ dara pọ̀ mọ́ àwọn onísìn mìíràn ni o tàbí ńṣe la wulẹ̀ tòrò mọ́ àwọn èrò tiwa nípa ìsìn, ìyẹn kò jẹ́ nǹkankan lójú Sátánì. Ṣùgbọ́n ohun tó ṣe pàtàkì tó ń fẹ́ ni pé ká má sin Jèhófà lọ́nà tí Ọlọ́run là sílẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀.

9. Báwo ni Sátánì ṣe ń lo ìbálòpọ̀ lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ?

9 Sátánì tún máa ń fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀ mú káwọn èèyàn tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn lọ́nà tí kò tọ́. Ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ takọtabo ló fi ń ṣe èyí. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé ti pa ẹ̀kọ́ rere tó wà nínú Bíbélì tì, wọ́n máa ń wo ìbálòpọ̀ láàárín àwọn èèyàn tí kò tíì ṣègbéyàwó bíi fàájì tí kò burú, tàbí bí ọ̀nà láti fi hàn pé àwọn náà ti dàgbà. Àwọn tó sì ti ṣègbéyàwó ńkọ́? Ọ̀pọ̀ wọn ló ń ṣe panṣágà. Àní nígbà tí ọkọ tàbí aya wọn kò bá tiẹ̀ ṣèṣekúṣe pàápàá, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wá ìkọ̀sílẹ̀ tàbí ìpínyà kí wọ́n lè lọ máa bá ẹlòmíràn gbé. Sátánì ń lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti mú kí àwọn èèyàn máa gbé ìgbé ayé fàájì nísinsìnyí. Ó ń mú kí wọ́n dágunlá sí àwọn àbájáde ọlọ́jọ́ pípẹ́ tó máa gbẹ̀yìn rẹ̀, kì í ṣe lórí àwọn àtàwọn ẹlòmíràn nìkan, àmọ́ ní pàtàkì jù lọ, lórí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Gálátíà 6:7, 8.

10. Àwọn nǹkan wo ni Sátánì máa ń lò láti rí i pé òún sọ èrò wa nípa ìṣekúṣe àti ìwà ipá dìdàkudà?

10 Ohun mìíràn tí ẹ̀dá tún fẹ́ràn ni eré ìtura. Bí eré ìtura bá gbámúṣé, ó máa ń mú kára tù wá, ọpọlọ wa á jí pépé, á sì mú kí ọkàn wa fúyẹ́. Àmọ́ báwo la ṣe máa ń ṣe nígbà tí Sátánì bá lo àkókò eré ìtura lọ́nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti sọ ìrònú wa di èyí tí kò bá ti Ọlọ́run mu mọ́? Bí àpẹẹrẹ, a mọ̀ pé Jèhófà kórìíra ìṣekúṣe àti ìwà ipá. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá gbé wọn jáde nínú sinimá, lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí nílé ìwòran, ṣé ńṣe la máa jókòó pa, tá a ó sì máa wò ó? Tún fi sọ́kàn pé, Sátánì á rí i dájú pé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ túbọ̀ burú sí i bí àkókò tí a ó fi í sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ti ń sún mọ́lé, nítorí pé “àwọn afàwọ̀rajà yóò [ti] máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà, a ó sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.” (2 Tímótì 3:13; Ìṣípayá 20:1-3) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò ní gbogbo ìgbà ká má bàa kó sínú àwọn ọ̀fìn tí Sátánì ń lò.—Jẹ́nẹ́sísì 6:13; Sáàmù 11:5; Róòmù 1:24-32.

11. Àwọn ọ̀nà wo ni ẹnì kan tó mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa ìbẹ́mìílò lè gbà di ẹni tí a rí mú bí kò bá wà lójúfò?

11 A tún mọ̀ pé Jèhófà kórìíra àwọn tó bá ń lọ́wọ́ nínú ìwà ìbẹ́mìílò lọ́nà èyíkéyìí. Ì báà jẹ́ iṣẹ́ wíwò, tàbí àjẹ́ ṣíṣe ni o, tàbí gbígbìyànjú láti bá òkú sọ̀rọ̀. (Diutarónómì 18:10-12) Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn wa, a ò ní í ronú láti tọ àwọn abẹ́mìílò lọ, ó sì dájú pé a ò ní gbà wọ́n láyè láti wá sínú ilé wa láti ṣe àwọn iṣẹ́ ẹ̀mí èṣù wọn. Àmọ́ bí wọ́n bá fara hàn lórí tẹlifíṣọ̀n wa tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ṣé ó yẹ ká tẹ́tí sí wọn? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò jẹ́ tọ babaláwo lọ fún ìtọ́jú, ṣé ó wá yẹ ká so okùn tín-ín-rín mọ́ ọrùn ọwọ́ ọmọ wa tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, ká máa lérò pé ó lè dáàbò bo ọmọ náà lọ́wọ́ ewu lọ́nà kan ṣá? Bí a ti mọ̀ pé Bíbélì sọ pé a kò gbọ́dọ̀ fi èèdì di àwọn ẹlòmíràn, ṣe ó wá yẹ ká jẹ́ kí múyèmúyè mú iyè wa lọ?—Gálátíà 5:19-21.

12. (a) Báwo ni Sátánì ṣe ń lo orin láti mú ká máa ronú lórí àwọn ohun tá a mọ̀ pé kò tọ́? (b) Báwo ni aṣọ ẹnì kan, ọ̀nà tó ń gbà ṣe irun rẹ̀ tàbí bó ṣe ń sọ̀rọ̀ ṣe ń fi hàn pé ó ń gbóṣùbà fún àwọn tí Jèhófà kórìíra ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbésí ayé? (d) Tá ò bá fẹ́ kó sí akóló àwọn ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí Sátánì, kí la gbọ́dọ̀ ṣe?

12 Bíbélì sọ pé a kò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ dárúkọ àgbèrè àti gbogbo onírúurú ìwà àìmọ́ rárá (pẹ̀lú ète búburú lọ́kàn) láàárín wa. (Éfésù 5:3-5) Àmọ́ tó bá jẹ́ àárín orin kan tó dùn, tí ìró rẹ̀ ń lọ sókè-sódò lọ́nà tó ń gbádùn mọ́ni tàbí tó ń kọ lálá ni irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lọ wà ńkọ́? Ṣé àá wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn orin tó ń gbé ìbálòpọ̀ láìṣe ìgbéyàwó, lílo oògùn olóró fún ìgbádùn, àtàwọn iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn lárugẹ? Àbí kẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a mọ̀ pé a kò gbọ́dọ̀ fara wé ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn èèyàn tó ń ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, ṣe a máa ń fẹ́ fi hàn pé a gba tiwọn nípa mímúra bí wọ́n ṣe ń múra, ṣíṣe irun bíi tiwọn tàbí sísọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀? Àwọn ọ̀nà tí Sátánì ń lò láti tan àwọn èèyàn jẹ, kí ìrònú tiwọn náà lè dìdàkudà bíi tirẹ̀ mà kúkú kún fún àrékérekè o! (2 Kọ́ríńtì 4:3, 4) Tá ò bá fẹ́ kó sí akóló àwọn ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ṣíṣe bí àwọn aráyé ṣe ń ṣe. A gbọ́dọ̀ máa rántí àwọn tó jẹ́ “olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí” ká sì máa jà fitafita kí wọ́n má bàa nípa lórí wa.—1 Pétérù 5:8.

A Mú Wa Gbára Dì Láti Jẹ́ Aṣẹ́gun

13. Báwo ló ṣe lè ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni nínú wa, pẹ̀lú bá a ṣe jẹ́ aláìpé tó, láti ṣẹ́gun ayé tí Sátánì ń ṣàkóso rẹ̀ yìí?

13 Kí Jésù tó kú, ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòhánù 16:33) Àwọn náà lè ṣẹ́gun ayé. Ní nǹkan bí ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ta ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ayé bí kò ṣe ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́ pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run?” (1 Jòhánù 5:5) À ń fi irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ hàn nígbà tí a bá ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jésù tá a sì ń gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àní gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe. Kí ló tún yẹ ká ṣe? A tún gbọ́dọ̀ fara mọ́ ìjọ tí Jésù jẹ́ Orí fún tímọ́tímọ́. Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, a gbọ́dọ̀ fi tọkàntọkàn ronú pìwà dà ká sì bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì Ọlọ́run lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ Jésù. Lọ́nà yìí, láìka ti àìpé wa àti àwọn àṣìṣe wa sí, àwa náà lè ṣẹ́gun ayé.—Sáàmù 130:3, 4.

14. Ka Éfésù 6:13-17, kí o sì fi àwọn ìbéèrè àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ìpínrọ̀ yìí ṣe ìpìlẹ̀ fún jíjíròrò àwọn àǹfààní tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìhámọ́ra tẹ̀mí náà ní.

14 Láti ṣàṣeyọrí, a gbọ́dọ̀ gbé “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” wọ̀, láìyọ ọ̀kankan sílẹ̀. Jọ̀wọ́ ṣí Bíbélì rẹ sí Éfésù 6:13-17, kí o sì kà nípa bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe ṣàpèjúwe ìhámọ́ra yẹn. Lẹ́yìn náà, dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e, kó o wá ṣàyẹ̀wò bí o ṣe lè jàǹfààní látinú ààbò tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìhámọ́ra náà ń pèsè.

‘Abẹ́nú tí a fi òtítọ́ dì lámùrè’

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè mọ ohun tí òtítọ́ jẹ́, báwo ni kíkẹ́kọ̀ọ́ déédéé, ṣíṣàṣàrò lórí òtítọ́ Bíbélì, àti lílọ sí ìpàdé ṣe ń dáàbò bò wá? (1 Kọ́ríńtì 10:12, 13; 2 Kọ́ríńtì 13:5; Fílípì 4:8, 9)

“Àwo ìgbàyà ti òdodo”

Ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo ta ni èyí jẹ́? (Ìṣípayá 15:3)

Sọ àpẹẹrẹ bí kíkọ̀ láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà ṣe lè fi ẹnì kan sínú ewu. (Diutarónómì 7:3, 4; 1 Sámúẹ́lì 15:22, 23)

‘Ẹsẹ̀ tí a fi ohun ìṣiṣẹ́ ìhìn rere àlàáfíà wọ̀ ní bàtà’

Báwo ni fífi ẹsẹ̀ wa rìn lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn ní gbogbo ìgbà, láti sọ fún wọn nípa àwọn ìpèsè tí Ọlọ́run ṣe fún àlàáfíà ṣe ń dáàbò bò wá? (Sáàmù 73:2, 3; Róòmù 10:15; 1 Tímótì 5:13)

“Apata ńlá ti ìgbàgbọ́”

Tí ìgbàgbọ́ wa bá fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa, kí la máa ṣe tá a bá dojú kọ àwọn ipò tó fẹ́ mú ká máa ṣiyèméjì tàbí ká bẹ̀rù? (2 Àwọn Ọba 6:15-17; 2 Tímótì 1:12)

“Àṣíborí ìgbàlà”

Báwo ni ìrètí ìgbàlà ṣe lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti yẹra fún dídi ẹni tó kó sí ọ̀fìn ṣíṣàníyàn kọjá bó ṣe yẹ nítorí àwọn ohun ìní ti ara? (1 Tímótì 6:7-10, 19)

“Idà ẹ̀mí”

Kí ló yẹ́ ká máa gbára lé ní gbogbo ìgbà tá a bá ń gbìyànjú láti já ara wa gbà lọ́wọ́ àwọn ohun tó ń wu ipò tẹ̀mí wa tàbí ti àwọn ẹlòmíràn léwu? (Sáàmù 119:98; Òwe 3:5, 6; Mátíù 4:3, 4)

Nǹkan mìíràn wo ló tún ṣe pàtàkì láti borí nínú ogun tẹ̀mí? Báwo ló ṣe yẹ ká máa lò ó déédéé sí? Nítorí àwọn wo? (Éfésù 6:18, 19)

15. Báwo la ṣe lè ṣe gbogbo ohun tó bá gbà nínú ìjà tẹ̀mí yìí?

15 Bí a ti jẹ́ ọmọ ogun Kristi, a wà lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá kan tó ń jagun tẹ̀mí. Bí a bá wà lójúfò tí a sì ń lo gbogbo ìhámọ́ra tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run dáadáa, a ò ní ṣòfò ẹ̀mí nínú ogun yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, a óò jẹ́ ìrànwọ́ fún àwọn tá a jọ jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, a ó sì fún wọn lókun. A óò múra tán a óò sì máa hára gàgà láti ṣe gbogbo ohun tó bá gbà láti tan ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run ti Mèsáyà náà kálẹ̀, ìyẹn ìṣàkóso ti ọ̀run tí Sátánì ń gbógun tì lójú méjèèjì.

Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò

• Kí ló mú kí àwọn olùjọsìn Jèhófà máa bá a nìṣó láìdá sí tọ̀tún-tòsì nínú àwọn rògbòdìyàn ayé?

• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tí Sátánì ń lò láti ba ipò tẹ̀mí àwọn Kristẹni jẹ́ ráúráú?

• Báwo ni ìhámọ́ra tẹ̀mí tí Ọlọ́run pèsè ṣe ń pa wá mọ́ nínú ogun tẹ̀mí wa?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 76]

À ń gbá àwọn orílẹ̀-èdè jọ sí Amágẹ́dọ́nì