“Wọn Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”
Orí Kejìdínlógún
“Wọn Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”
1. (a) (a) Kí Jésù tó kú, àdúrà wo ló gbà nítorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? (b) Èé ṣe tí ṣíṣàì jẹ́ “apá kan ayé” fi ṣe pàtàkì gan-an?
NÍ ALẸ́ tí Jésù lò kẹ́yìn kí wọ́n tó pa á, ó gbàdúrà nítorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Níwọ̀n bí Jésù ti mọ̀ pé Sátánì máa gbé ìṣòro líle koko dìde sí wọn, ó sọ fún Baba rẹ̀ pé: “Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé, bí kò ṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà. Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:15, 16) Kí nìdí tí yíya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé fi ṣe pàtàkì gan-an? Ó jẹ́ nítorí pé Sátánì ni alákòóso ayé. Àwọn Kristẹni kò ní fẹ́ di apá kan ayé tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀.—Lúùkù 4:5-8; Jòhánù 14:30; 1 Jòhánù 5:19.
2. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jésù kì í fi í ṣe apá kan ayé?
2 Ṣíṣàì jẹ́ apá kan ayé kò túmọ̀ sí pé Jésù kò nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mú àwọn aláìsàn lára dá, ó jí òkú dìde, ó sì kọ́ àwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ó tiẹ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ìran ènìyàn pàápàá. Àmọ́, kò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀mí àìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti ìwà táwọn tó ní ẹ̀mí ayé Sátánì ń hù. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe kìlọ̀kìlọ̀ nípa àwọn nǹkan bí ìfẹ́ ìṣekúṣe, ọ̀nà ìgbésí ayé onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, àti dídu ipò ọlá. (Mátíù 5:27, 28; 6:19-21; Lúùkù 20:46, 47) Abájọ tí Jésù fi yẹra fún ìṣèlú ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Júù ni, kò dá sí tọ̀túntòsì nínú àìgbọ́ra-ẹni-yé lórí ọ̀ràn ìṣèlú tó wà láàárín Róòmù àtàwọn Júù nígbà yẹn.
“Ìjọba Mi Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé Yìí”
3. (a) Ẹ̀sùn wo làwọn aṣáájú ìsìn Júù fi kan Jésù níwájú Pílátù, èé sì ti ṣe? (b) Kí ló fi hàn pé Jésù kò nífẹ̀ẹ́ sí dídi ọba ènìyàn?
3 Ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn aṣáájú ìsìn Júù mú Jésù lọ síwájú Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ gómìnà Róòmù. Ní ti tòótọ́, nítorí pé Jésù ti tú àgàbàgebè àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn fó ni inú ṣe ń bí wọn. Kí gómìnà náà lè dá Jésù lẹ́bi, wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé: “A rí ọkùnrin yìí tí ń dojú orílẹ̀-èdè wa dé, tí ó sì ń ka sísan owó orí fún Késárì léèwọ̀, tí ó sì ń sọ pé òun fúnra òun ni Kristi ọba.” (Lúùkù 23:2) Ó ṣe kedere pé irọ́ gbáà nìyí nítorí pé ọdún kan ṣáájú àkókò yẹn ni wọ́n fẹ́ fi Jésù jọba, tó kọ̀. (Jòhánù 6:15) Ó mọ̀ pé òun máa di Ọba ní ọ̀rún lọ́jọ́ iwájú. (Lúùkù 19:11, 12) Àti pé ènìyàn kọ́ ló máa fi òun jọba, bí kò ṣe Jèhófà.
4. Kí ni ìṣarasíhùwà Jésù sí sísan owó orí?
4 Ní ọjọ́ mẹ́ta ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n mú Jésù yẹn, àwọn Farisí gbìyànjú láti mú kí Jésù sọ ohun kan tí wọ́n máa rí gbá mú lórí ọ̀ràn sísan owó orí. Àmọ́ ó sọ pé: “Ẹ fi owó dínárì kan hàn mí [ìyẹn ẹyọwó àwọn Róòmù]. Àwòrán àti àkọlé ta ni ó ní?” Nígbà tí wọ́n wí pé: “Ti Késárì,” ó fèsì pé: “Ẹ rí i dájú, nígbà náà, pé ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”—Lúùkù 20:20-25.
5. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àkókò tí wọ́n mú un? (b) Báwo ni Jésù ṣe ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe ohun tó ṣe? (d) Kí ni àbájáde ìgbẹ́jọ́ yẹn?
5 Rárá o, Jésù kò fi ṣíṣọ̀tẹ̀ sí àwọn aláṣẹ kọ́ni. Nígbà táwọn ọmọ ogun àtàwọn mìíràn wá mú Jésù, Pétérù fa idà yọ, ó ṣá ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin náà, ó sì gé etí rẹ̀ dà nù. Àmọ́ Jésù sọ pé: “Dá idà rẹ padà sí Mátíù 26:51, 52) Ní ọjọ́ kejì, Jésù ṣàlàyé ìdí tó fi gbé ìgbésẹ̀ yẹn fún Pílátù, ó ní: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà kí a má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́.” (Jòhánù 18:36) Pílátù gbà pé kò sí “ìdí kankan fún àwọn ẹ̀sùn” tí wọ́n fi kan Jésù. Àmọ́ nítorí pé àwọn jàǹdùkú náà pin ín lẹ́mìí, Pílátù ní kí wọn kan Jésù mọ́gi.—Lúùkù 23:13-15; Jòhánù 19:12-16.
àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Tẹ̀ Lé Ìdarí Jésù
6. Báwo làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe fi hàn pé àwọn yẹra fún ẹ̀mí ayé ṣùgbọ́n tí wọ́n fi hàn pé àwọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn?
6 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wá tipa bẹ́ẹ̀ lóye ohun tí ṣíṣàì jẹ́ apá kan ayé béèrè. Ó túmọ̀ sí yíyàgò fún ẹ̀mí àti ìwà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run táwọn èèyàn ayé ní, èyí tó kan ìwà ipá àti eré ìnàjú oníṣekúṣe níbi ìran àpéwò ìta gbangba àti ní gbọ̀ngàn ìṣeré àwọn ará Róòmù. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní àwọn tó kórìíra aráyé. Àmọ́, wọn ò kórìíra ọmọnìkejì wọn rárá, dípò ìyẹn ńṣe ni wọ́n ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní nínú ètò tí Ọlọ́run ṣe fún ìgbàlà.
7. (a) Kí ni ojú àwọn ọmọ ẹ̀yìn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ rí nítorí pé wọn kì í ṣe apá kan ayé? (b) Ojú wo ni wọ́n fi wo àwọn alákòóso ìṣèlú àti sísan owó orí, kí sì nìdí?
7 Wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù bí wọ́n ṣe ṣe sí òun alára, ọ̀pọ̀ ìgbà ní inúnibíni náà máa ń wá látọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ ìjọba táwọn èèyàn parọ́ fún. Síbẹ̀, ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù, ó ń rọ̀ wọ́n láti “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga [àwọn òṣèlú], nítorí kò Róòmù 13:1-7; Títù 3:1, 2.
sí ọlá àṣẹ kankan bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Kì í ṣe pé Jèhófà ló gbé àwọn ìjọba ayé kalẹ̀ o, àmọ́ ó fàyè gbà wọ́n láti wà níbẹ̀ títí dìgbà tí Ìjọba rẹ̀ nìkan ṣoṣo yóò máa ṣàkóso lórí gbogbo ilẹ̀ ayé. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún àwọn tó wà nípò àṣẹ, kí wọ́n sì máa san owó orí.—8. (a) Ibo ló yẹ káwọn Kristẹni fi ìtẹríba wọn fún àwọn aláṣẹ onípò gíga mọ sí? (b) Báwo làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?
8 Àmọ́ ṣá o, títẹríba fún àwọn alákòóso ìṣèlú gbọ́dọ̀ ní ààlà, ó ní ibi tó mọ. Nígbà tí òfin Jèhófà àti tèèyàn bá forí gbárí, àwọn tó ń sin Jèhófà gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí àwọn òfin Rẹ̀. Kíyè sí ohun tí ìwé On the Road to Civilization—A World History sọ nípa àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, ó ní: “Àwọn Kristẹni kọ̀ láti kópa nínú àwọn ojúṣe kan tó jẹ́ ti àwọn aráàlú Róòmù. Àwọn Kristẹni . . . gbà pé ńṣe làwọn sẹ́ ìgbàgbọ́ àwọn táwọn bá wọnú iṣẹ́ ológun. Wọn kì í tẹ́wọ́ gba ipò òṣèlú. Wọn kì í jọ́sìn olú-ọba.” Nígbà tí ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù “pa àṣẹ” fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn “ní pàtó” pé kí wọn ṣíwọ́ wíwàásù, wọ́n fèsì pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:27-29.
9. (a) Kí nìdí táwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù fi gbé ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa? (b) Ọ̀nà wo nìyẹn gbà jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára?
9 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn kò dá sí tọ̀tún tòsì rárá nínú ọ̀ràn ìṣèlú àti ti ológun. Lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa, àwọn Júù tó wà ní Jùdíà ṣọ̀tẹ̀ sí Késárì. Kíá làwọn ọmọ ogun Róòmù yí Jerúsálẹ́mù ká. Kí làwọn Kristẹni tó Lúùkù 21:20-24) Àìdásí-tọ̀túntòsì wọn jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn Kristẹni tòótọ́ lẹ́yìn náà.
wà nílùú náà ṣe? Wọ́n rántí ìmọ̀ràn tí Jésù fún wọn pé kí wọ́n sá kúrò ní ìlú náà. Bí àwọn ará Róòmù ṣe kógun wọn kúrò fúngbà díẹ̀ báyìí ni àwọn Kristẹni sá gba Odò Jọ́dánì kọjá lọ sí àwọn ilẹ̀ olókè ńláńlá Pella. (Àìdásí-tọ̀túntòsì Kristẹni Láwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Wọ̀nyí
10. (a) Iṣẹ́ wo ló ń jẹ́ kí ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dí, èé sì ti ṣe? (b) Inú ọ̀ràn wo ni wọ́n ti jẹ́ aláìdásí-tọ̀túntòsì?
10 Ǹjẹ́ ìtàn tó wà lákọọ́lẹ̀ fi hàn pé àwùjọ èyíkéyìí ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí ti wà láìdásí-tọ̀túntòsì ní àfarawé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe bẹ́ẹ̀. Gbogbo wọn ló ń wàásù lákòókò tá a wà yìí pé Ìjọba Ọlọ́run ni ọ̀nà kan ṣoṣo láti fún àwọn olùfẹ́ òdodo ní àlàáfíà, aásìkí, àti ayọ̀ pípẹ́ títí. (Mátíù 24:14) Àmọ́ wọn ò dá sí ọ̀kankan nínú àìgbọ́ra-ẹni-yé tó ń lọ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.
11. (a) Báwo ni àìdásí-tọ̀túntòsì àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe yàtọ̀ pátápátá sí ohun táwọn àlùfáà ń ṣe? (b) Ìhà wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ sí ohun táwọn ẹlòmíràn ń ṣe nípa ìṣèlú?
11 Ní òdì kejì pátápátá sí ìyẹn, àwùjọ àlùfáà inú àwọn ẹ̀sìn ayé yìí ti lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn ìṣèlú gan-an. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n ti fi gbogbo ipá wọn polongo ìbò fún àwọn olóṣèlú kan, tàbí kí wọ́n ṣe àtakò àwọn kan. Àwọn àlùfáà kan tiẹ̀ gba ipò òṣèlú. Àwọn kan ti fòòró ẹ̀mí àwọn olóṣèlú láti tẹ́wọ́ gbà àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí àwùjọ àlùfáà fọwọ́ sí. Àmọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò lọ́wọ́ sí ìṣèlú rárá. Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sọ pé kí ẹni tó bá fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú má ṣe bẹ́ẹ̀, wọn ò ní káwọn ẹlòmíì má du ipò ìṣèlú, wọ́n ò sì ní kí ẹni tó bá fẹ́ dìbò má ṣe bẹ́ẹ̀.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í kópa nínú ìṣèlú nítorí Jésù ti sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun kò ní jẹ́ apá kan ayé.12. Kí ló ti ṣẹlẹ̀ nítorí pé àwọn ẹ̀sìn ayé yìí ń dá sí ọ̀ràn ogun?
12 Bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè ò yéé jagun. Kódà àwọn ẹgbẹ́ kan máa ń gbógun ja àwọn ẹgbẹ́ mìíràn láàárín orílẹ̀-èdè kan náà. (Mátíù 24:3, 6, 7) Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn aṣáájú ìsìn máa ń ti orílẹ̀-èdè kan tàbí ẹgbẹ́ kan lẹ́yìn láti gbógun ti òmíràn, tí wọ́n á sì máa rọ àwọn ọmọlẹ́yìn wọn láti ṣe bákan náà. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Àwọn ẹlẹ́sìn kan náà máa ń para wọn lójú ogun kìkì nítorí pé orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀yà wọ́n yàtọ̀ síra. Èyí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu rárá.—1 Jòhánù 3:10-12; 4:8, 20.
13. Kí ni ẹ̀rí fi hàn nípa àìdásí-tọ̀túntòsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
13 Àmọ́ ṣá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jẹ́ aláìdásí-tọ̀túntòsì pátápátá nínú gbogbo ìforígbárí tó wáyé. Ilé Ìṣọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì ti November 1, 1939, sọ pé: “Gbogbo àwọn tó wà níhà ọ̀dọ̀ Olúwa yóò jẹ́ aláìdásí-tọ̀túntòsì àwọn orílẹ̀-èdè tó ń bára wọn jagun.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè àti lábẹ́ onírúurú ipò ń bá a lọ láti mú ìpinnu yìí ṣẹ. Wọn ò jẹ́ kí ọ̀ràn ìṣèlú ayé tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ àti ogun tú ẹgbẹ́ ará wọn tó kárí ayé ká. Wọ́n “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọ́n . . . sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn.” Nítorí pé wọn kì í dá sí tọ̀túntòsì, wọn ò kọ́ ogun jíjà mọ́.—Aísáyà 2:3, 4; 2 Kọ́ríńtì 10:3, 4.
14. Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí yíyà tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé?
14 Kí ni ọkàn lára ohun tí àìdásí-tọ̀túntòsì wọn ti fà? Jésù sọ pé: “Nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, . . . ni ayé fi kórìíra yín.” (Jòhánù 15:19) Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n ti jù sẹ́wọ̀n nítorí pé wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n ti dá àwọn kan lóró, kódà wọ́n ti pa àwọn kan pàápàá, gẹ́gẹ́ bó ti ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Ohun tó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rí bẹ́ẹ̀ ni pé Sátánì, “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” ń tako àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, tí wọn kì í ṣe apá kan rẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 4:4; Ìṣípayá 12:12.
15. (a) Ibo ni gbogbo orílẹ̀-èdè ń yan lọ, kí sì ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi tìṣọ́ratìṣọ́ra yẹra fún? (b) Èé ṣe tí yíyara ẹni sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé fi jẹ́ ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì gan-an?
15 Inú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà dùn pé àwọn kì í ṣe apá kan ayé, nítorí pé gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà nínú rẹ̀ ló ń yan lọ sí òpin wọn ní Amágẹ́dọ́nì. (Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 16:14, 16; 19:11-21) A óò bọ́ lọ́wọ́ ìparun yẹn nítorí tí a ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé. Gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn tó wà ní ìṣọ̀kan kárí ayé, a dúró ṣinṣin ti Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run. Lóòótọ́, bí a ò ṣe jẹ́ apá kan ayé ń mú káwọn èèyàn fi wá ṣẹ̀sín, kí wọ́n sì máa ṣe inúnibíni sí wa. Àmọ́, ìyẹn yóò dópin láìpẹ́, nítorí pé ayé búburú ìsinsìnyí tó wà lábẹ́ Sátánì yóò pa run títí láé. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, àwọn tó sin Jèhófà yóò wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun òdodo lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.—2 Pétérù 3:10-13; 1 Jòhánù 2:15-17.
Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò
• Báwo ni Jésù ṣe fi ṣíṣàì jẹ́ “apá kan ayé” hàn?
• Kí ni ìṣarasíhùwà àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ sí (a) ẹ̀mí ayé? (b) àwọn alákòóso ayé, àti (d) sísan owó orí?
• Àwọn ọ̀nà wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ń gbà fi ẹ̀rí àìdásí-tọ̀túntòsì Kristẹni wọn hàn?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 165]
Jésù ṣàlàyé pé òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn òun “kì í ṣe apá kan ayé”