Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ọba tí Ń Figẹ̀ Wọngẹ̀ Wọ Ọ̀rúndún Ogún

Àwọn Ọba tí Ń Figẹ̀ Wọngẹ̀ Wọ Ọ̀rúndún Ogún

Orí Kẹẹ̀ẹ́dógún

Àwọn Ọba tí Ń Figẹ̀ Wọngẹ̀ Wọ Ọ̀rúndún Ogún

1. Àwọn wo ni òpìtàn kan sọ pé wọ́n jẹ́ aṣáájú ilẹ̀ Yúróòpù ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún?

ÒPÌTÀN Norman Davies kọ̀wé pé: “Irú ìgbòkègbodò kíkankíkan tí ó wáyé ní ilẹ̀ Yúróòpù ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí.” Ó fi kún un pé: “Ńṣe ni agbára ń gorí agbára ní ilẹ̀ Yúróòpù lọ́nà tí ó ju ti ìgbàkigbà rí lọ: agbára ìmọ̀ ẹ̀rọ, agbára ọrọ̀ ajé, agbára àṣà ìbílẹ̀, agbára lórí àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lókè òkun.” Davies sọ pé àwọn tí wọ́n jẹ́ aṣáájú nígbà “‘ọ̀rúndún ìlépa agbára’ tí ó ṣàṣeyọrí ní Yúróòpù ni, àkọ́kọ́, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì . . . àti fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ilẹ̀ Jámánì.”

WỌ́N “NÍ ÌTẸ̀SÍ ṢÍṢE OHUN BÚBURÚ”

2. Bí ọ̀rúndún kọkàndínlógún ṣe parí, àwọn agbára ayé wo ni wọ́n bọ́ sípò “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù”?

2 Ní ìgbà tí ọ̀rúndún kọkàndínlógún ń parí lọ, Ilẹ̀ Ọba Jámánì ni “ọba àríwá,” ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sì wà nípò “ọba gúúsù.” (Dáníẹ́lì 11:14, 15) Áńgẹ́lì Jèhófà sọ pé: “Ní ti ọba méjì yìí, ọkàn-àyà wọn yóò ní ìtẹ̀sí ṣíṣe ohun búburú, àti ní tábìlì kan náà, wọn yóò máa pa irọ́.” Ó tẹ̀ síwájú pé: “Ṣùgbọ́n nǹkan kan kì yóò kẹ́sẹ járí, nítorí òpin ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀.”—Dáníẹ́lì 11:27.

3, 4. (a) Ta ní di ọba àkọ́kọ́ nínú Ìjọba Jámánì, àjọṣepọ̀ wo ni a sì ṣe? (b) Ìlànà ìṣèlú wo ni Kaiser Wilhelm bẹ̀rẹ̀ sí lò?

3 Ní January 18, 1871, Wilhelm Kìíní di ọba àkọ́kọ́ ní Ìjọba, tàbí Ilẹ̀ Ọba, Jámánì. Ó yan Otto von Bismarck sípò olórí ìjọba. Góńgó Bismarck ni láti mú kí ìdàgbàsókè bá ilẹ̀ ọba tuntun yìí, nítorí náà, ó yẹra fún ìforígbárí pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, ó sì bá orílẹ̀-èdè Austria òun Hungary àti Ítálì wọ àjọṣe, tí a wá mọ̀ sí Àdéhùn Orílẹ̀-Èdè Mẹ́ta. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, ohun tí ọba àríwá tuntun yìí fẹ́ ṣe forí gbárí pẹ̀lú ohun tí ọba gúúsù ń fẹ́.

4 Lẹ́yìn ikú Wilhelm Kìíní àti ti Frederick Kẹta tí ó jẹ́ arọ́pò rẹ̀ lọ́dún 1888, Wilhelm Kejì, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, gorí ìtẹ́. Wilhelm Kejì, tàbí Kaiser Wilhelm, fipá mú kí Bismarck fiṣẹ́ sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìlànà mímú kí ibi tí agbára ilẹ̀ Jámánì dé túbọ̀ gbòòrò sí i lágbàáyé. Òpìtàn kan sọ pé: “Lábẹ́ àkóso Wilhelm Kejì, ẹ̀mí ìgbéraga àti jàgídíjàgan gun ilẹ̀ [Jámánì].”

5. Báwo ni ọba méjèèjì ṣe jókòó sídìí “tábìlì kan,” kí sì ni wọ́n ń sọ níbẹ̀?

5 Nígbà tí Níkólásì Kejì Olú Ọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà pe ìpè fún ìpàdé àpérò fún àlàáfíà ní ìlú Hague, ilẹ̀ Netherlands, ní August 24, 1898, ṣe ni ọ̀ràn gbóná girigiri láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Ìpàdé àpérò yìí àti èyí tí ó tẹ̀ lé e lọ́dún 1907 ni ó fìdí Ilé Ẹjọ́ Wíwàpẹ́títí fun Ìparí Ìjà ní Hague múlẹ̀. Bí Ìjọba Jámánì àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pẹ̀lú ṣe di mẹ́ńbà ilé ẹjọ́ yìí, ńṣe ni wọ́n ń fi yéni pé àwọn fara mọ́ àlàáfíà. Wọ́n jùmọ̀ jókòó sídìí “tábìlì kan náà,” ní ṣíṣe bíi pé wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́, àmọ́, ‘ọkàn-àyà wọn ní ìtẹ̀sí ṣíṣe ohun búburú.’ Títa ọgbọ́n féfé nípa ‘pípa irọ́ nídìí tábìlì kan náà’ kò lè mú kí àlàáfíà tòótọ́ wà. “Nǹkan kan kì yóò kẹ́sẹ járí,” nínú góńgó tí wọ́n ń lépa nínú ọ̀ràn ìṣèlú, ọrọ̀ ajé, àti tí ọ̀ràn ológun, nítorí pé òpin àwọn ọba méjèèjì ‘ṣì jẹ́ fún àkókò tí Jèhófà Ọlọ́run yàn kalẹ̀.’

Ó “LÒDÌ SÍ MÁJẸ̀MÚ MÍMỌ́”

6, 7. (a) Lọ́nà wo ni ọba àríwá gbà “padà lọ sí ilẹ̀ rẹ̀”? (b) Kí ni ìṣarasíhùwà ọba gúúsù ní ti bí agbára ọba àríwá ṣe ń gbòòrò sí i?

6 Áńgẹ́lì Ọlọ́run ń bá a lọ pé: “Òun [ọba àríwá] yóò sì padà lọ sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ẹrù púpọ̀ rẹpẹtẹ, ọkàn-àyà rẹ̀ yóò sì lòdì sí májẹ̀mú mímọ́. Yóò sì gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́, dájúdájú, yóò sì padà lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.”—Dáníẹ́lì 11:28.

7 Kaiser Wilhelm padà lọ sí “ilẹ̀” tàbí ipò inú ayé, tí ọba àríwá àtijọ́ wà. Báwo? Nípa pé ó gbé ìṣàkóso ilẹ̀ ọba kan kalẹ̀, èyí tí ó wéwèé láti fi mú kí Ìjọba Jámánì gbòòrò sí i kí ó sì mú kí agbára rẹ̀ gbilẹ̀ sí i. Wilhelm Kejì sapá láti ní àwọn ilẹ̀ tí yóò máa tòkèèrè ṣàkóso lé lórí ní Áfíríkà àti ní àwọn ibòmíràn. Ó kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun ojú omi alágbára jọ láti lè figẹ̀ wọngẹ̀ pẹ̀lú àwọn ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí ó jẹ́ ọ̀gá lójú omi. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Láàárín ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ju ọdún mẹ́wàá péré lọ, ẹgbẹ́ ọmọ ogun ojú omi ilẹ̀ Jámánì, tí a kò fi bẹ́ẹ̀ kà sí tẹ́lẹ̀, wá di alágbára débi pé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nìkan ni ó ṣáájú rẹ̀.” Ó wá di dandan pé kí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì mú ìṣètò ẹgbẹ́ ọmọ ogun ojú omi tirẹ̀ gbòòrò sí i láti lè máa wà nípò ọ̀gá lọ. Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tún lọ bá ilẹ̀ Faransé ṣàdéhùn ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ (ìfọwọ́sowọ́pọ̀), ó sì bá ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe irú àdéhùn kan náà, tí ó fi wá di Àdéhùn Ọ̀rẹ́ Mẹ́ta. A wá pín ilẹ̀ Yúróòpù sí ibùdó ẹgbẹ́ ọmọ ogun méjì wàyí—àwọn tó ṣe Àdéhùn Orílẹ̀-Èdè Mẹ́ta wà níhà kan, àwọn tó ṣe Àdéhùn Ọ̀rẹ́ Mẹ́ta sì wà níhà kejì.

8. Báwo ni Ilẹ̀ Ọba Jámánì ṣe wá ní “ẹrù púpọ̀ rẹpẹtẹ”?

8 Ìlànà ìṣèlú tí kò gba gbẹ̀rẹ́ ni Ilẹ̀ Ọba Jámánì ń lò, èyí sì mú kí ilẹ̀ Jámánì ní “ẹrù púpọ̀ rẹpẹtẹ” nítorí pé ilẹ̀ Jámánì ni baba ìsàlẹ̀ nídìí Àdéhùn Orílẹ̀-Èdè Mẹ́ta. Ilẹ̀ Austria òun Hungary àti Ítálì jẹ́ orílẹ̀-èdè ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì. Nítorí náà, póòpù fojú rere wo Àdéhùn Orílẹ̀-Èdè Mẹ́ta náà, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọba gúúsù àti àwọn tí ó bá a ṣe Àdéhùn Ọ̀rẹ́ Mẹ́ta, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn kì í ti í ṣe ẹlẹ́sìn Kátólíìkì.

9. Báwo ni ọba àríwá ṣe “lòdì sí májẹ̀mú mímọ́” náà ní ọkàn-àyà rẹ̀?

9 Àwọn ènìyàn Jèhófà wá ńkọ́? Tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n ti ń polongo pé “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” yóò dópin ní ọdún 1914. * (Lúùkù 21:24) Lọ́dún yẹn, a fìdí Ìjọba Ọlọ́run tí ó wà lọ́wọ́ Jésù Kristi, Ajogún Dáfídì Ọba, múlẹ̀ ní ọ̀run. (2 Sámúẹ́lì 7:12-16; Lúùkù 22:28, 29) Láti March 1880 lọ́hùn-ún ni ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti máa ń sọ pé ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run ní í ṣe pẹ̀lú òpin “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè,” tàbí “akoko awọn Keferi.” (Bíbélì Mímọ́) Ṣùgbọ́n ọkàn-àyà ọba àríwá ti ilẹ̀ Jámánì “lòdì sí májẹ̀mú mímọ́” ti Ìjọba Ọlọ́run. Dípò kí Kaiser Wilhelm gbà pé Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso, ṣe ló “gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́,” nípa gbígbé ìhùmọ̀ rẹ̀ láti ṣàkóso ayé lárugẹ. Àmọ́, ṣíṣe tí ó ṣe bẹ́ẹ̀, egbìnrìn ọ̀tẹ̀ tí ó yọrí sí Ogun Àgbáyé Kìíní ló gbìn.

“ÌDORÍKODÒ” BÁ ỌBA YẸN NÍGBÀ OGUN

10, 11. Báwo ni Ogun Àgbáyé Kìíní ṣe bẹ̀rẹ̀, báwo ni èyí sì ṣe bọ́ sí “àkókò tí a yàn kalẹ̀”?

10 Áńgẹ́lì náà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní àkókò tí a yàn kalẹ̀, òun [ọba àríwá] yóò padà, òun yóò sì wá lòdì sí gúúsù ní ti gidi; ṣùgbọ́n kì yóò rí ní ìkẹyìn bí ó ti rí ní àkọ́kọ́.” (Dáníẹ́lì 11:29) “Àkókò” tí Ọlọ́run “yàn kalẹ̀” láti fòpin sí ìṣàkóso àwọn Kèfèrí lórí ayé dé ní ọdún 1914, nígbà tí ó gbé Ìjọba ọ̀run kalẹ̀. Lọ́dún yẹn, ní June 28, apániláyà kan, ará Serbia, pa Francis Ferdinand Ọmọ Ọba Austria àti aya rẹ̀ ní ìlú Sarajevo, ilẹ̀ Bosnia. Èyí ni ó tanná ran ẹ̀tù Ogun Àgbáyé Kìíní.

11 Kaiser Wilhelm rọ ilẹ̀ Austria òun Hungary pé kí wọ́n gbẹ̀san lára ilẹ̀ Serbia. Bí ilẹ̀ Jámánì ṣe mú un dá ilẹ̀ Austria òun Hungary lójú pé òun wà lẹ́yìn rẹ̀, lòun náà bá kéde ogun sí ilẹ̀ Serbia ní July 28, 1914. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ Rọ́ṣíà ran ilẹ̀ Serbia lọ́wọ́. Nígbà tí ilẹ̀ Jámánì kéde ogun sí ilẹ̀ Rọ́ṣíà, ilẹ̀ Faransé (tí wọ́n jùmọ̀ jẹ́ alájọṣe nínú Àdéhùn Ọ̀rẹ́ Mẹ́ta) ran ilẹ̀ Rọ́ṣíà lọ́wọ́. Ni ilẹ̀ Jámánì bá kéde ogun sí ilẹ̀ Faransé. Kí ó lè rọ ilẹ̀ Jámánì lọ́rùn láti dé ìlú Paris, ó gbógun ja ilẹ̀ Belgium tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti fọwọ́ sọ̀yà fún pé kò dá sí tọ̀tún tòsì. Bí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe kéde ogun sí ilẹ̀ Jámánì nìyẹn. Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn kó wọnú ogun náà, ilẹ̀ Ítálì wá kẹ̀yìn sí ìhà tí ó wà tẹ́lẹ̀. Nígbà ogun yẹn, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ ilẹ̀ Íjíbítì di orílẹ̀-èdè tí ó wà lábẹ́ ààbò rẹ̀ kí ọba àríwá má bàa lọ dí Ọ̀nà Ojú Omi Suez kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ gbé ogun ja ilẹ̀ Íjíbítì, tí ó jẹ́ ilẹ̀ ọba gúúsù látijọ́.

12. Nígbà ogun àgbáyé kìíní, ọ̀nà wo ni àwọn nǹkan kò gbà “rí ní ìkẹyìn bí ó ti rí ní àkọ́kọ́”?

12 Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Láìka bí àwọn Apawọ́pọ̀jagun ṣe lágbára tó, ó dà bí pé ilẹ̀ Jámánì fẹ́rẹ̀ẹ́ borí nínú ogun náà.” Nínú àwọn gídígbò ọba méjèèjì látẹ̀yìnwá, Ilẹ̀ Ọba Róòmù gẹ́gẹ́ bí ọba àríwá, ni ó máa ń ṣẹ́gun gbogbo rẹ̀. Àmọ́, lọ́tẹ̀ yìí, ‘nǹkan kò rí bí ó ti ń rí ní àkọ́kọ́.’ A ṣẹ́gun ọba àríwá. Áńgẹ́lì náà sọ ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ pé: “Dájúdájú, àwọn ọkọ̀ òkun àwọn ará Kítímù yóò gbéjà kò ó, ìdoríkodò yóò sì bá a.” (Dáníẹ́lì 11:30a) Kí ni “àwọn ọkọ̀ òkun àwọn ará Kítímù”?

13, 14. (a) Ní pàtàkì, kí ni “àwọn ọkọ̀ òkun àwọn ará Kítímù” tí ó wá gbéjà ko ọba àríwá? (b) Báwo ni àwọn ọkọ̀ òkun àwọn ará Kítímù púpọ̀ sí i ṣe wá nígbà tí ogun àgbáyé kìíní ń bá a lọ?

13 Nígbà ayé Dáníẹ́lì, ilẹ̀ Kípírọ́sì ni Kítímù. Nígbà tí ogun àgbáyé kìíní fi máa bẹ̀rẹ̀, abẹ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni ilẹ̀ Kípírọ́sì wà. Ní àfikún sí i, bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Zondervan Pictorial Encyclopedia of the Bible ṣe sọ, orúkọ náà Kítímù “ni a tún ń lò fún Ìwọ̀ Oòrùn ní gbogbo gbòò, pàápàá ìhà Ìwọ̀ Oòrùn tí ó gbajúmọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ọkọ̀ òkun.” Bíbélì New International Version túmọ̀ gbólóhùn náà “àwọn ọkọ̀ òkun àwọn ará Kítímù” sí “ọkọ̀ òkun àwọn ilẹ̀ etíkun ìhà ìwọ̀ oòrùn.” Nígbà ogun àgbáyé kìíní, àwọn ọkọ̀ òkun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn etíkun ilẹ̀ Yúróòpù ni àwọn ọkọ̀ òkun Kítímù ní pàtàkì.

14 Bí ogun náà ṣe ń falẹ̀ sí i, àwọn ọkọ̀ òkun Kítímù púpọ̀ sí i wá láti ṣètìlẹyìn fún Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ojú Omi Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ní May 7, 1915, ọkọ̀ abẹ́ omi ti ilẹ̀ Jámánì tí ń jẹ́ U-20 ri ọkọ̀ ojú omi akérò náà Lusitania ní ìhà gúúsù etíkun ilẹ̀ Ireland. Àwọn ará Amẹ́ríkà méjìdínláàádóje sì wà lára àwọn tó kú. Lẹ́yìn náà, ilẹ̀ Jámánì gbé ogun tí ó ń fi ọkọ̀ abẹ́ omi jà dé ojú òkun Àtìláńtíìkì. Nítorí èyí, ní April 6, 1917, Ààrẹ Woodrow Wilson ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kéde ogun sí ilẹ̀ Jámánì. Bí ọkọ̀ ogun ojú omi àti àwọn ọmọ ogun Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe gbárùkù ti ọba gúúsù—tí í ṣe Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà báyìí—òun àti ọba àríwá tí ń bá a figẹ̀ wọngẹ̀ wá kúkú wàákò gidi.

15. Ìgbà wo ni “ìdoríkodò” bá ọba àríwá?

15 Bí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ṣe gbógun ti ọba àríwá, ni “ìdoríkodò” bá bá a, bí ó ṣe juwọ́ sílẹ̀ tipátipá nìyẹn ní November 1918. Wilhelm Kejì fẹsẹ̀ fẹ lọ sí ilẹ̀ Netherlands, ni ilẹ̀ Jámánì bá di orílẹ̀-èdè aláìlọ́ba. Àmọ́, ọ̀ràn ọba àríwá kò parí síbẹ̀.

ỌBA NÁÀ “GBÉ ÌGBÉSẸ̀ LỌ́NÀ TÍ Ó GBÉṢẸ́”

16. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe fi hàn, báwo ni ọba àríwá yóò ṣe hùwà sí bí a ṣe ṣẹ́gun rẹ̀?

16 “Òun [ọba àríwá] yóò sì padà ní ti tòótọ́, yóò sì fi ìdálẹ́bi sọ̀kò sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà tí ó gbéṣẹ́; òun yóò sì ní láti padà, yóò sì fún àwọn tí ń fi májẹ̀mú mímọ́ sílẹ̀ ní àfiyèsí.” (Dáníẹ́lì 11:30b) Bí áńgẹ́lì náà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nìyẹn, ó sì ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.

17. Kí ló ṣokùnfà ìdìde Adolf Hitler?

17 Lẹ́yìn tí ogun yẹn parí lọ́dún 1918, àwọn Apawọ́pọ̀jagun tí wọ́n ṣẹ́gun, gbé àdéhùn àlàáfíà ìfìyàjẹni ka ilẹ̀ Jámánì lórí. Àwọn ará ilẹ̀ Jámánì rí i pé ohun tí àdéhùn náà ń béèrè lọ́dọ̀ àwọn le koko, bẹ́ẹ̀, orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di aláìlọ́ba yìí ṣì jẹ́ aláìlágbára. Ilẹ̀ Jámánì ráre fún ọ̀pọ̀ ọdún, Ìlọsílẹ̀ Ọrọ̀ Ajé Ńláǹlà sì bá a, tí ó fi jẹ́ pé àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà mẹ́fà ènìyàn ni kò ríṣẹ́ ṣe. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1930, bí ipò àwọn nǹkan ṣe rí mú kí dídé tí Adolf Hitler dé orí àlééfà bọ́ sí àkókò. Ó di olórí ìjọba ní January 1933, lọ́dún tó tẹ̀ lé e ó sì bọ́ sípò ààrẹ ìjọba tí àwọn Násì pè ní Ìjọba Kẹta. *

18. Báwo ni Hitler ṣe “gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà tí ó gbéṣẹ́”?

18 Gbàrà tí Hitler gorí àlééfà ló bá kọjú ìjà kíkorò sí “májẹ̀mú mímọ́” tí àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù Kristi ń ṣojú fún. (Mátíù 25:40) Ní ti èyí, ó “gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà tí ó gbéṣẹ́” lòdì sí àwọn Kristẹni adúróṣinṣin wọ̀nyí, ní ṣíṣe inúnibíni kíkorò sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn. Hitler ṣe àwọn àṣeyọrí nínú ọ̀ràn ọrọ̀ ajé àti ti ìṣèlú, ó sì tún “gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà tí ó gbéṣẹ́” ní ìhà wọ̀nyẹn pẹ̀lú. Láàárín ọdún mélòó kan, ó sọ ilẹ̀ Jámánì di ilẹ̀ tí a kò lè fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn lágbàáyé.

19. Bí Hitler ṣe ń wá alátìlẹyìn, ta ni ó fà mọ́ra?

19 Hitler “fún àwọn tí ń fi májẹ̀mú mímọ́ sílẹ̀ ní àfiyèsí.” Ta ni àwọn wọ̀nyí? Ó dájú pé àwọn aṣáájú Kirisẹ́ńdọ̀mù ni, àwọn ẹni tí wọ́n sọ pé àwọn bá Ọlọ́run dá májẹ̀mú ṣùgbọ́n tí wọn kì í ṣe ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi mọ́. Hitler ké sí “àwọn tí ń fi májẹ̀mú mímọ́ sílẹ̀” yìí pé kí wọ́n ṣètìlẹyìn fún òun, ó sì ṣàṣeyọrí. Bí àpẹẹrẹ, òun àti póòpù jùmọ̀ wọ àdéhùn ìmùlẹ̀ ní ìlú Róòmù. Ní ọdún 1935, Hitler dá Ilé-Iṣẹ́ Tó Ń Rí Sí Ọ̀ràn Ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀. Ọ̀kan lára góńgó rẹ̀ ni pé kí ó mú kí Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Ajíhìnrere wà lábẹ́ àkóso ìjọba.

“ÀWỌN APÁ” JÁDE WÁ LÁTI Ọ̀DỌ̀ ỌBA

20. “Àwọn apá” wo ni ọba àríwá lò, ní ìlòdì sí ta sì ni?

20 Láìpẹ́, Hitler wá bẹ̀rẹ̀ ogun jíjà, gan-an bí áńgẹ́lì náà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ lọ́nà tí ó péye pé: “Àwọn apá yóò sì dìde, láti ọ̀dọ̀ rẹ̀; ní ti tòótọ́, wọn yóò sọ ibùjọsìn, odi agbára di aláìmọ́, wọn yóò sì mú apá pàtàkì ìgbà gbogbo kúrò.” (Dáníẹ́lì 11:31a) “Àwọn apá” náà ni agbo ọmọ ogun tí ọba àríwá lò láti fi bá ọba gúúsù jà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ní September 1, 1939, “àwọn apá” ti Násì gbógun ja ilẹ̀ Poland. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Faransé kéde ogun sí ilẹ̀ Jámánì láti lè ran ilẹ̀ Poland lọ́wọ́. Bí Ogun Àgbáyé Kejì ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Kíá ni a ṣẹ́gun ilẹ̀ Poland, kété lẹ́yìn náà, agbo ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì gba ilẹ̀ Denmark, Norway, Netherlands, Belgium, Luxembourg, àti ilẹ̀ Faransé. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Nígbà ìparí ọdún 1941, ìjọba Násì ti Jámánì ni ó jọba lé gbogbo ilẹ̀ Yúróòpù lórí.”

21. Báwo ni nǹkan ṣe yíwọ́ fún ọba àríwá nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, kí ni ó sì wá yọrí sí?

21 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ Jámánì àti ilẹ̀ Soviet Union ti jùmọ̀ fọwọ́ sí Àdéhùn Ìbáraṣọ̀rẹ́, Ìfọwọ́sowọ́pọ̀, àti ti Ojú Ààlà, Hitler ṣì lọ gbé ogun ja ìpínlẹ̀ ilẹ̀ Soviet ní June 22, 1941. Ìgbésẹ̀ yìí ló mú kí ilẹ̀ Soviet Union bọ́ sí ìhà ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Gbágbáágbá ni agbo ọmọ ogun ilẹ̀ Soviet dènà wọn láìka ti pé agbo ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì tètè ráyè wọ̀ wọ́n lára lákọ̀ọ́kọ́ sí. Ní December 6, 1941, a fojú agbo ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì gbolẹ̀ ní Moscow. Lọ́jọ́ kejì, ilẹ̀ Japan tí ó jẹ́ olùgbèjà ilẹ̀ Jámánì, ju bọ́ǹbù sí ìlú Pearl Harbor, ní Hawaii. Bí èyí ṣe détí ìgbọ́ Hitler, ní ó bá sọ fún àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé: “Wàyí o, a kò lè pàdánù ogun yìí mọ́.” Ní December 11, ó fi ìwàǹwára kéde ogun sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àmọ́, ńṣe ló fojú di agbára ilẹ̀ Soviet Union àti ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Bí agbo ọmọ ogun Soviet ṣe gbógun tì wọ́n níhà ìlà oòrùn tí ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà sì ń wọlé sí wọn lára bọ̀ níhà ìwọ̀ oòrùn, nǹkan bá yíwọ́ fún Hitler. Àwọn ibi tí ilẹ̀ Jámánì ti ṣẹ́gun wá bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́ lọ́kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn tí Hitler ti pa ara rẹ̀, ilẹ̀ Jámánì túúbá fún àwọn Apawọ́pọ̀jagun ní May 7, 1945.

22. Báwo ni ọba àríwá ṣe ‘sọ ibùjọsìn di aláìmọ́, tí ó sì mú apá pàtàkì ìgbà gbogbo kúrò’?

22 Áńgẹ́lì náà sọ pé: “Ní ti tòótọ́, wọn [àwọn apá Násì] yóò sọ ibùjọsìn, odi agbára di aláìmọ́, wọn yóò sì mú apá pàtàkì ìgbà gbogbo kúrò.” Ní ìlú Júdà ìgbàanì, ibùjọsìn jẹ́ ara tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Àmọ́, nígbà tí àwọn Júù kọ Jésù sílẹ̀, Jèhófà kọ àwọn àti tẹ́ńpìlì wọn sílẹ̀. (Mátíù 23:37–24:2) Láti ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ni tẹ́ńpìlì Jèhófà ní ti gidi, ọ̀run sì ni ibi mímọ́ nínú àwọn ibi mímọ́ rẹ̀ wà, tí àgbàlá rẹ̀ nípa tẹ̀mí sì wà lórí ilẹ̀ ayé, inú rẹ̀ ni àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù, Olórí Àlùfáà ti ń sìn. Láti àwọn ọdún 1930 síwájú ni àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti ń jọ́sìn pa pọ̀ pẹ̀lú àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró, ìyẹn ni a fi sọ pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ‘nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run.’ (Ìṣípayá 7:9, 15; 11:1, 2; Hébérù 9:11, 12, 24) Ọba àríwá sọ àgbàlá tẹ́ńpìlì náà ti orí ilẹ̀ ayé di aláìmọ́ ní àwọn ilẹ̀ tí ó wà níkàáwọ́ rẹ̀ nípa ṣíṣe inúnibíni lemọ́lemọ́ sí àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn. Inúnibíni náà le koko tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi di pé a mú “apá pàtàkì ìgbà gbogbo”—ẹbọ ìyìn ní gbangba sí orúkọ Jèhófà—kúrò. (Hébérù 13:15) Àmọ́, láìka ìjìyà bíburú jáì sí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́ pẹ̀lú àwọn “àgùntàn mìíràn” ń bá a lọ láti wàásù nígbà Ogun Àgbáyé Kejì.—Jòhánù 10:16.

‘A GBÉ OHUN ÌRÍRA NÁÀ KALẸ̀’

23. Kí ni “ohun ìríra” náà ní ọ̀rúndún kìíní?

23 Nígbà tí ogun àgbáyé kejì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí, ohun mìíràn ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ bí áńgẹ́lì Ọlọ́run ṣe sọ tẹ́lẹ̀. “Dájúdájú, wọn yóò gbé ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro kalẹ̀.” (Dáníẹ́lì 11:31b) Jésù pẹ̀lú sọ̀rọ̀ nípa “ohun ìríra” náà. Ní ọ̀rúndún kìíní, òun ni agbo ọmọ ogun ilẹ̀ Róòmù tí ó wá sí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa láti wá paná ọ̀tẹ̀ tí àwọn Júù gbé dìde. *Mátíù 24:15; Dáníẹ́lì 9:27.

24, 25. (a) Kí ni “ohun ìríra” náà ní òde òní? (b) Ìgbà wo ni a ‘gbé ohun ìríra náà kalẹ̀,’ báwo ni a sì ṣe gbé e kalẹ̀?

24 Kí ni “ohun ìríra” tí a ‘gbé kalẹ̀’ ní òde òní? Ó dájú pé ohun “ìríra” ti ayédèrú Ìjọba Ọlọ́run ni. Èyíinì ni Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tí ó lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, tàbí tí jíjẹ́ tí ó jẹ́ àjọ àlàáfíà àgbáyé dópin nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀. (Ìṣípayá 17:8) Àmọ́ ṣá, “ẹranko ẹhànnà” náà yóò “gòkè wá láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.” Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí a fìdí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, tí àádọ́ta orílẹ̀-èdè títí kan ilẹ̀ Soviet Union tẹ́lẹ̀ jẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀, múlẹ̀ ní October 24, 1945. Bí a ṣe gbé “ohun ìríra”—Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè—tí áńgẹ́lì náà sọ tẹ́lẹ̀ kalẹ̀ nìyẹn.

25 Ilẹ̀ Jámánì ni ó jẹ́ òléwájú nínú àwọn ọ̀tá ọba gúúsù nígbà ogun àgbáyé méjèèjì, òun ni ó sì ti wà nípò ọba àríwá. Ta ni yóò tún wá bọ́ síbẹ̀ báyìí?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 9 Wo Orí Kẹfà ìwé yìí.

^ ìpínrọ̀ 17 Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ ni ìjọba àkọ́kọ́, Ilẹ̀ Ọba Jámánì sì ni ìkejì.

^ ìpínrọ̀ 23 Wo Orí Kọkànlá ìwé yìí.

KÍ LO LÓYE?

• Nígbà òpin ọ̀rúndún kọkàndínlógún, àwọn agbára wo ni wọ́n bọ́ sípò ọba àríwá àti ti ọba gúúsù?

• Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, báwo ni àbájáde gídígbò ọba méjèèjì kò ṣe “rí ní ìkẹyìn bí ó ti rí ní àkọ́kọ́” fún ọba àríwá?

• Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, báwo ni Hitler ṣe sọ ilẹ̀ Jámánì di agbára tí a kò lè fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ọ̀ràn àgbáyé?

• Kí ni àbáyọrí ìfigẹ̀wọngẹ̀ ọba àríwá àti ti gúúsù nígbà Ogun Àgbáyé Kejì?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 268]

ÀWỌN ỌBA INÚ DÁNÍẸ́LÌ 11:27-31

Ọba Àríwá Ọba Gúúsù

Dáníẹ́lì 11:27-30a Ilẹ̀ Ọba Jámánì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, lẹ́yìn náà ni

(Ogun Àgbáyé Kìíní) Agbára Ayé

Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà

Dáníẹ́lì 11:30b, 31 Ìjọba Jámánì Kẹta Agbára Ayé

ti Hitler

(Ogun Àgbáyé Kejì) Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà

[Àwòrán]

Ààrẹ Woodrow Wilson pẹ̀lú Ọba George Karùn-ún

[Àwòrán]

Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ni a ṣe inúnibíni sí nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́

[Àwòrán]

Àwọn aṣáájú Kirisẹ́ńdọ̀mù kọ́wọ́ ti Hitler lẹ́yìn

[Àwòrán]

Inú ọkọ̀ tí a ti ṣìkà pa Ọmọọba Ferdinand

[Àwòrán]

Àwọn sójà ilẹ̀ Jámánì, Ogun Àgbáyé Kìíní

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 257]

Ní ìlú Yalta, lọ́dún 1945, Olórí Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Winston Churchill, Ààrẹ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, Franklin D. Roosevelt, àti Olórí Ìjọba ilẹ̀ Soviet, Joseph Stalin, fohùn ṣọ̀kan lórí ìwéwèé láti gba ilẹ̀ Jámánì, láti dá ìjọba tuntun sílẹ̀ ní Poland, àti láti ṣèpàdé láti dá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 258]

1. Ọmọọba Ferdinand 2. Ọmọ ogun ojú omi ilẹ̀ Jámánì 3. Ọmọ ogun ojú omi ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì 4. Ọkọ̀ òkun Lusitania 5. Ìkéde Ogun ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 263]

Adolf Hitler ní ìdánilójú pé òun yóò ṣẹ́gun lẹ́yìn tí ilẹ̀ Japan, tí ó jẹ́ olùgbèjà ilẹ̀ Jámánì nígbà ogun, ju bọ́ǹbù sí Pearl Harbor