Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn tí A Mọ̀ Sí Ọba Méjèèjì yí Padà

Àwọn tí A Mọ̀ Sí Ọba Méjèèjì yí Padà

Orí Kẹrìnlá

Àwọn tí A Mọ̀ Sí Ọba Méjèèjì yí Padà

1, 2. (a) Kí ló fà á tí Áńtíókọ́sì Kẹrin fi juwọ́ sílẹ̀ tí ó sì ṣe bí Róòmù ṣe wí? (b) Ìgbà wo ni Síríà di ìgbèríko Róòmù?

ÁŃTÍÓKỌ́SÌ Kẹrin ọba Síríà gbé ogun ja Íjíbítì, ó sì fi ara rẹ̀ jẹ ọba ibẹ̀. Pẹ́tólẹ́mì Kẹfà ọba Íjíbítì bá ní kí ilẹ̀ Róòmù ránni sí òun, ilẹ̀ Róòmù bá rán Káúsì Pópílíù Láénásì, ikọ̀ rẹ̀, lọ sí Íjíbítì. Ọ̀wọ́ ọkọ̀ okun rẹpẹtẹ ni ó bá a wá, àṣẹ alágbára tí ó gbà wá láti Ilé Aṣòfin Àgbà ní Róòmù ni pé kí Áńtíókọ́sì Kẹrin sọ pé òun kì í ṣe ọba Íjíbítì mọ́ kí ó sì fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀. Ìlú Éléúsísì, tí ó wà ní eréko Alẹkisáńdíríà, ni ọba Síríà àti ikọ̀ Róòmù ti fojú kojú. Áńtíókọ́sì Kẹrin sọ pé kí wọ́n fún òun láyè láti lọ fọ̀rọ̀ lọ àwọn ìgbìmọ̀ òun, ṣùgbọ́n Láénásì fa ìlà yí po ọba yẹn, ó sì sọ fún un pé kí ó dáhùn kí ó tó dá ìlà yẹn kọjá. Bí ẹ̀tẹ́ ṣe bá Áńtíókọ́sì Kẹrin, ó ṣe ohun tí Róòmù wí, ó sì padà sí Síríà ní ọdún 168 ṣááju Sànmánì Tiwa. Bí ìfigẹ̀wọngẹ̀ ọba àríwá ti Síríà àti ọba gúúsù ti Íjíbítì ṣe dópin nìyẹn.

2 Bí Róòmù ṣe ń kó ipa pàtàkì jù lọ nínú àlámọ̀rí Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, ó bẹ̀rẹ̀ sí pàṣẹ wàá fún Síríà. Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọba mìíràn tí ń jẹ́ Sẹ̀lẹ́úkọ́sì ń ṣàkóso Síríà lẹ́yìn ikú Áńtíókọ́sì Kẹrin ní ọdún 163 ṣááju Sànmánì Tiwa, wọn kò sí ní ipò “ọba àríwá.” (Dáníẹ́lì 11:15) Níkẹyìn, lọ́dún 64 ṣááju Sànmánì Tiwa, Síríà di ọ̀kan lára ìgbèríko Róòmù.

3. Ìgbà wo ni Róòmù borí ilẹ̀ Íjíbítì, báwo ni ó sì ṣe borí rẹ̀?

3 Ìlà àwọn ọba tí ń jẹ́ Pẹ́tólẹ́mì ní Íjíbítì ń bá a lọ ní ipò “ọba gúúsù” fún ohun tí ó fi díẹ̀ ju àádóje ọdún lẹ́yìn ikú Áńtíókọ́sì Kẹrin. (Dáníẹ́lì 11:14) Nígbà ogun Ákítíọ́mù, lọ́dún 31 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ọkitéfíà olùṣàkóso Róòmù ṣẹ́gun àpapọ̀ agbo ọmọ ogun ọbabìnrin tí ó jẹ kẹ́yìn ní ìlà àwọn ọba tí ń jẹ́ Pẹ́tólẹ́mì—Kilẹopátírà Keje—àti ti Máàkù Áńtónì, àlè rẹ̀ tó jẹ́ ará Róòmù. Lẹ́yìn tí Kilẹopátírà pa ara rẹ̀ ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, Íjíbítì pẹ̀lú di ọ̀kan nínú ìgbèríko Róòmù, kò sì kó ipa ọba gúúsù mọ́. Nígbà tí ó fi máa di ọdún 30 ṣááju Sànmánì Tiwa, Róòmù ti borí Síríà àti Íjíbítì. Ṣé kí a máa retí pé kí àwọn ìjọba mìíràn bẹ̀rẹ̀ sí kó ipa ọba àríwá àti ti ọba gúúsù wàyí?

ỌBA TUNTUN KAN RÁN “AFIPÁMÚNI” JÁDE

4. Èé ṣe tí a fi lè retí pé kí alákòóso mìíràn bọ́ sípò ọba àríwá?

4 Nígbà ìrúwé ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù Kristi sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nígbà tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nípasẹ̀ Dáníẹ́lì wòlíì, . . . nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.” (Mátíù 24:15, 16) Bí Jésù ṣe fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Dáníẹ́lì 11:31, ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro” tí yóò wà lọ́jọ́ iwájú. A sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ọba àríwá yìí ní nǹkan bí igba ọdún ó dín márùn-ún lẹ́yìn ikú Áńtíókọ́sì Kẹrin, ọba Síríà tí ó kó ipa ọba àríwá kẹ́yìn. Dájúdájú, alákòóso mìíràn ní láti bọ́ sí ipò ọba àríwá. Ta ni yóò jẹ́?

5. Ta ní dìde gẹ́gẹ́ bí ọba àríwá, tí ó wá bọ́ sí ipò tí Áńtíókọ́sì Kẹrin wà tẹ́lẹ̀?

5 Áńgẹ́lì Jèhófà Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ẹnì kan yóò . . . dìde ní ipò rẹ̀ [ipò Áńtíókọ́sì Kẹrin], ẹni tí ń mú kí afipámúni la ìjọba ọlọ́lá ńlá náà kọjá, àti ní ìwọ̀n ọjọ́ díẹ̀ a óò ṣẹ́ ẹ, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú ìbínú tàbí nínú ogun.” (Dáníẹ́lì 11:20) Ẹ̀rí fi hàn pé ẹni tí ó “dìde” lọ́nà yìí ni Ọkitéfíà, tí a mọ̀ sí Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì, olú ọba àkọ́kọ́ ní Róòmù.—Wo “A Bọlá fún Ọ̀kan, A Tẹ́ńbẹ́lú Ìkejì,” ní ojú ìwé 248.

6. (a) Ìgbà wo ni a mú kí “afipámúni” la “ìjọba ọlọ́lá ńlá” kọjá, kí sì ni ìjẹ́pàtàkì èyí? (b) Èé ṣe tí a fi lè sọ pé ikú Ọ̀gọ́sítọ́sì “kì í ṣe nínú ìbínú tàbí nínú ogun”? (d) Àyípadà wo ló ṣẹlẹ̀ ní ti ẹni tí a mọ̀ sí ọba àríwá?

6 “Ilẹ̀ Ìṣelóge”—ilẹ̀ Júdà tí ó jẹ́ ìgbèríko Róòmù—wà lára “ìjọba ọlọ́lá ńlá” tí ó jẹ́ ti Ọ̀gọ́sítọ́sì. (Dáníẹ́lì 11:16) Lọ́dún 2 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ọ̀gọ́sítọ́sì rán “afipámúni” jáde nípa pé ó pàṣẹ pé kí a ṣe ìforúkọsílẹ̀ tàbí ìkànìyàn, bóyá láti jẹ́ kí ó mọ iye àwọn olùgbé ilẹ̀ rẹ̀ nítorí ọ̀ràn owó orí àti láti múni wọṣẹ́ ológun. Nítorí àṣẹ yìí ni Jósẹ́fù àti Màríà fi rìnrìn àjò lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láti lọ forúkọ sílẹ̀, tí ó mú kí a bí Jésù síbẹ̀ bí a ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Míkà 5:2; Mátíù 2:1-12) Ní August ọdún 14 Sànmánì Tiwa—“ní ìwọ̀n ọjọ́ díẹ̀,” tàbí láìpẹ́ lẹ́yìn pípàṣẹ ìforúkọsílẹ̀ náà—Ọ̀gọ́sítọ́sì kú ní ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin, ikú rẹ̀ kì í ṣe nípasẹ̀ “ìbínú” láti ọwọ́ àwọn apànìyàn bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe “nínú ogun,” bí kò ṣe nípasẹ̀ àìsàn. Ní tòótọ́, ẹni tí a mọ̀ sí ọba àríwá ti yí padà! Nísinsìnyí, ọba yìí ti di Ilẹ̀ Ọba Róòmù, ìyẹn àwọn olú ọba rẹ̀.

‘ẸNI TÍ A TẸ́ŃBẸ́LÚ DÌDE’

7, 8. (a) Ta ní dìde ní ipò Ọ̀gọ́sítọ́sì gẹ́gẹ́ bí ọba àríwá? (b) Èé ṣe tí a fi fi ìlọ́tìkọ̀ gbé “iyì ìjọba náà” fún arọ́pò Ọ̀gọ́sítọ́sì Késárì?

7 Áńgẹ́lì náà ń bá àsọtẹ́lẹ̀ náà lọ pé: “Ẹnì kan tí a óò tẹ́ńbẹ́lú yóò sì dìde ní ipò rẹ̀ [ipò Ọ̀gọ́sítọ́sì], wọn kì yóò sì fi iyì ìjọba náà fún un; ní ti gidi, òun yóò wọlé lákòókò òmìnira kúrò lọ́wọ́ àníyàn, yóò sì gba ìjọba náà nípasẹ̀ ìpọ́nni dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in. Ní ti apá ìkún omi náà, wọn yóò sì kún àkúnya ní tìtorí rẹ̀, a ó sì ṣẹ́ wọn; bí a ó ti ṣẹ́ Aṣáájú májẹ̀mú náà pẹ̀lú.”—Dáníẹ́lì 11:21, 22.

8 “Ẹnì kan tí a óò tẹ́ńbẹ́lú” náà ni Tìbéríù Késárì, ọmọ Lífíà, tí ó jẹ́ aya kẹta fún Ọ̀gọ́sítọ́sì. (Wo “A Bọlá fún Ọ̀kan, A Tẹ́ńbẹ́lú Ìkejì,” ní ojú ìwé 248.) Ọ̀gọ́sítọ́sì kórìíra ọmọ tí aya rẹ̀ gbé wálé rẹ̀ yìí nítorí ìwàkíwà rẹ̀, kò sì fẹ́ kí ó di Késárì lẹ́yìn òun. Ìgbà tí ó di pé gbogbo àwọn yòókù tí ì bá bọ́ sípò náà kú ni a fi ìlọ́tìkọ̀ gbé “iyì ìjọba náà” fún un. Ọdún 4 Sànmánì Tiwa ni Ọ̀gọ́sítọ́sì gba Tìbéríù ṣọmọ tí ó sì sọ ọ́ di ajogún ìtẹ́. Lẹ́yìn ikú Ọ̀gọ́sítọ́sì, Tìbéríù—ẹni tí a tẹ́ńbẹ́lú—ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta “dìde,” ó sì gba agbára gẹ́gẹ́ bí olú ọba Róòmù àti gẹ́gẹ́ bí ọba àríwá.

9. Báwo ni Tìbéríù ṣe “gba ìjọba náà nípasẹ̀ ìpọ́nni dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in”?

9 Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Tìbéríù ta ọgbọ́n fún Ilé Aṣòfin Àgbà, kò sì jẹ́ kí wọ́n fi òun jẹ olú ọba fún ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó oṣù kan [lẹ́yìn ikú Ọ̀gọ́sítọ́sì].” Ó sọ fún Ilé Aṣòfin Àgbà pé kò tún sí ẹlòmíràn tí ó tóótun láti gbé ẹrù ìnira ti ṣíṣe àkóso Ilẹ̀ Ọba Róòmù yàtọ̀ sí Ọ̀gọ́sítọ́sì, ó sì sọ pé kí àwọn aṣòfin àgbà dá ìjọba padà sí ti àjùmọ̀ṣe nípa gbígbé ìjọba lé àwùjọ ènìyàn lọ́wọ́ dípò jíjẹ́ kí ẹnì kan ṣoṣo máa ṣe é. Òpìtàn Will Durant sọ pé: “Bí Ilé Aṣòfin Àgbà kò ti fẹ́ gba ohun tí ó wí wọlé rárá, àwọn àti òun wá jùmọ̀ ń tẹrí ba fún ara wọn títí tí ó fi wá tẹ́wọ́ gba agbára nígbẹ̀yìngbẹ́yín.” Durant fi kún un pé: “Ìhà méjèèjì rí ọgbọ́n yẹn ta fún ara wọn dáadáa. Tìbéríù ń wá ipò ìṣàkóso gíga jù lọ, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, ì bá ti wá ọ̀nà kan ṣáá láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀; Ilé Aṣòfin Àgbà bẹ̀rù rẹ̀ wọ́n sì kórìíra rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ń yẹra fún ohun tí ó lè mú kí wọ́n tún dá ìjọba àjùmọ̀ṣe, tí wọ́n ń ṣe látijọ́, padà sáàárín àwọn tí a kàn fẹnu pè ní ìgbìmọ̀ aláṣẹ gíga jù lọ.” Bí Tìbéríù ṣe “gba ìjọba náà nípasẹ̀ ìpọ́nni dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in” nìyẹn.

10. Báwo ni a ṣe ‘ṣẹ́ apá ìkún omi náà’?

10 Áńgẹ́lì náà sọ pé: “Ní ti apá ìkún omi náà”—agbo ọmọ ogun àwọn ìjọba tí ó yí wọn ká—‘wọn yóò kún àkúnya a ó sì ṣẹ́ wọn.’ Nígbà tí Tìbéríù di ọba àríwá, Jamaníkọ́sì Késárì ọmọ àbúrò rẹ̀ ni ọ̀gágun àwọn ọmọ ogun Róòmù tí ń bẹ lójú Odò Rhine. Lọ́dún 15 Sànmánì Tiwa, Jamaníkọ́sì kó agbo ọmọ ogun rẹ̀ lọ láti gbéjà ko Ámínọ́sì, akọni ará Jámánì kan, ó sì ṣàṣeyọrí díẹ̀. Àmọ́, àwọn ìṣẹ́gun tí kò tó nǹkan náà ná wọn ní nǹkan púpọ̀ gan-an, Tìbéríù bá ṣíwọ́ ogun jíjà ní ilẹ̀ Jámánì lẹ́yìn ìyẹn. Dípò èyí, nípa ṣíṣokùnfa ogun abẹ́lé ní Jámánì, ó gbìyànjú láti máà jẹ́ kí àwọn ẹ̀yà Jámánì wà ní ìṣọ̀kan. Ní gbogbo gbòò, ìlànà kí-ìṣòro-má-wọ̀lú ni Tìbéríù fara mọ́ nínú ọ̀nà tí ó gbà ń bá ìjọba ilẹ̀ òkèèrè lò, ó sì gbájú mọ́ mímú kí àwọn ààlà ilẹ̀ rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i. Ìgbésẹ̀ yìí sì kẹ́sẹ járí dáadáa. Lọ́nà yìí, “apá ìkún omi náà” ni a mú wá sábẹ́ àkóso tí a sì “ṣẹ́” wọn.

11. Báwo ni a ṣe “ṣẹ́ Aṣáájú májẹ̀mú náà”?

11 Bákan náà, a “ṣẹ́ Aṣáájú májẹ̀mú” tí Jèhófà Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá fún ìbùkún gbogbo ìdílé ayé. Jésù Kristi ni Irú-Ọmọ Ábúráhámù tí a ṣèlérí rẹ̀ nínú májẹ̀mú náà. (Jẹ́nẹ́sísì 22:18; Gálátíà 3:16) Ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù dúró síwájú Pọ́ńtíù Pílátù nínú ààfin gómìnà ará Róòmù ní Jerúsálẹ́mù. Ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ sí olú ọba ni àwọn àlùfáà Júù fi kan Jésù. Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún Pílátù pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. . . . Ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.” Kí gómìnà ará Róòmù náà má bàa dá Jésù tí ó jẹ́ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, àwọn Júù kígbe pé: “Bí ìwọ bá tú ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Késárì. Olúkúlùkù ènìyàn tí ó bá ń fi ara rẹ̀ jẹ ọba ń sọ̀rọ̀ lòdì sí Késárì.” Lẹ́yìn tí wọ́n sọ pé kí a pa Jésù, wọ́n sọ pé: “Àwa kò ní ọba kankan bí kò ṣe Késárì.” Níbàámu pẹ̀lú òfin “ọ̀tẹ̀ sí ìjọba,” èyí tí Tìbéríù ti fẹ̀ lójú débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kan ohunkóhun tí ó bá sáà ti tàbùkù sí Késárì, Pílátù fi Jésù lé wọn lọ́wọ́ láti “ṣẹ́” tàbí láti kàn mọ́ òpó igi oró.—Jòhánù 18:36; 19:12-16; Máàkù 15:14-20.

ÒǸRORÒ KAN ‘PÈTE PÈRÒ’

12. (a) Àwọn wo ni wọ́n bá Tìbéríù ní àjọṣepọ̀? (b) Báwo ni Tìbéríù ṣe “di alágbára ńlá nípasẹ̀ orílẹ̀-èdè kékeré”?

12 Bí áńgẹ́lì náà ṣe ń bá àsọtẹ́lẹ̀ náà lọ lórí Tìbéríù, ó sọ pé: “Nítorí àjọṣepọ̀ tí wọ́n ní pẹ̀lú rẹ̀, yóò máa bá a lọ ní ṣíṣe ẹ̀tàn, yóò sì gòkè wá ní ti gidi, yóò sì di alágbára ńlá nípasẹ̀ orílẹ̀-èdè kékeré.” (Dáníẹ́lì 11:23) Lábẹ́ òfin, àwọn mẹ́ńbà Ilé Aṣòfin Àgbà ní Róòmù ní “àjọṣepọ̀” pẹ̀lú Tìbéríù, òun náà sì gbára lé wọn bí òfin ṣe wí. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ẹlẹ́tàn, ó sì “di alágbára ńlá nípasẹ̀ orílẹ̀-èdè kékeré” ní tòótọ́. Orílẹ̀-èdè kékeré yẹn ni Ẹ̀ṣọ́ Ọba ní Róòmù, tí ó ní ibùdó sẹ́bàá odi ìlú Róòmù. Wíwà tí wọ́n wà nítòsí kò jẹ́ kí Ilé Aṣòfin Àgbà lè ṣe bó ṣe fẹ́, ó sì tún jẹ́ kí Tìbéríù lè paná ọ̀tẹ̀ èyíkéyìí tí àwọn ará ìlú bá fẹ́ gbé dìde sí àṣẹ rẹ̀. Nítorí náà, Tìbéríù ń bá a nìṣó ní jíjẹ́ alágbára ńlá nípasẹ̀ nǹkan bí ẹgbàárùn-ún ẹ̀ṣọ́.

13. Ọ̀nà wo ni Tìbéríù gbà tayọ àwọn baba ńlá rẹ̀?

13 Áńgẹ́lì náà fi àsọtẹ́lẹ̀ yìí kún un pé: “Lákòókò òmìnira kúrò lọ́wọ́ àníyàn, kódà òun yóò wọnú ọ̀rá àgbègbè abẹ́ àṣẹ, ní ti gidi yóò sì ṣe ohun tí àwọn baba rẹ̀ àti àwọn baba baba rẹ̀ kò ṣe. Yóò tú ohun tí a piyẹ́ àti ohun ìfiṣèjẹ àti àwọn ẹrù ká láàárín wọn; ìpètepèrò rẹ̀ yóò sì jẹ́ ní ìlòdìsí àwọn ibi olódi, ṣùgbọ́n títí di àkókò kan ni.” (Dáníẹ́lì 11:24) Ìfura Tìbéríù ti pọ̀ jù, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ènìyàn ni a sì fi àṣẹ ọba gbé lọ láti pa nígbà ìṣàkóso rẹ̀. Nítorí ìmọ̀ràn tí Séjánúsì, olórí àwọn Ẹ̀ṣọ́ Ọba ń gbà á ní pàtàkì, apá ìkẹyìn ìjọba rẹ̀ di ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀. Níkẹyìn, ó fura sí Séjánúsì alára, ó sì ní kí a pa á. Ní ti híhùwà òǹrorò sí àwọn ènìyàn, Tìbéríù tayọ àwọn baba ńlá rẹ̀.

14. (a) Báwo ni Tìbéríù ṣe tú “ohun tí a piyẹ́ àti ohun ìfiṣèjẹ àti àwọn ẹrù ká” gbogbo ìgbèríko ilẹ̀ Róòmù? (b) Irú ènìyàn wo ni a ka Tìbéríù sí nígbà tí ó fi máa kú?

14 Àmọ́ ṣá, Tìbéríù tú “ohun tí a piyẹ́ àti ohun ìfiṣèjẹ àti àwọn ẹrù ká” gbogbo ìgbèríko Róòmù. Nígbà tó fi máa kú, gbogbo ènìyàn ìjọba rẹ̀ ni nǹkan rọ̀ ṣọ̀mù fún. Owó orí kò pọ̀, a sì máa lawọ́ sí àwọn àgbègbè tí nǹkan kò bá ti fara rọ. Bí àwọn ọmọ ogun tàbí òṣìṣẹ́ ọba bá tẹ ẹnikẹ́ni lórí ba tàbí tí wọ́n bá hùwàkiwà lẹ́nu iṣẹ́ wọn, wọ́n mọ̀ pé ẹ̀san lè wá sórí wọn láti ọ̀dọ̀ ọba. Kíkáwọ́ tí ó káwọ́ ìjọba rẹ̀ gírígírí mú kí ìfọ̀kànbalẹ̀ wà láwùjọ, ètò ìbánisọ̀rọ̀ tí a mú sunwọ̀n sí i sì mú kí ètò ìṣòwò túbọ̀ dára. Tìbéríù rí i dájú pé kò sí ojúsàájú tàbí ségesège ní ti bí a ṣe ń bójú tó àwọn ọ̀ràn nínú Róòmù àti nílẹ̀ òkèèrè. Nípa mímú kí àwọn ètò àtúnṣe tí Ọ̀gọ́sítọ́sì Késárì gbé kalẹ̀ túbọ̀ tẹ̀ síwájú, a mú àwọn òfin sunwọ̀n sí i, ìlànà ìwà rere àti ìwà ọmọlúwàbí láwùjọ ní a sì mú kí ó dára sí i. Síbẹ̀, Tìbéríù ‘pète pèrò,’ tí Tásítọ́sì, òpìtàn ará Róòmù náà, fi wá ṣàpèjúwe rẹ̀ pé ó jẹ́ alágàbàgebè, tí ó mọ bí a ti ń fẹ̀jẹ̀ sínú tutọ́ funfun jáde dáadáa. Nígbà tí Tìbéríù fi máa kú ní March ọdún 37 Sànmánì Tiwa, òǹrorò ẹ̀dá ni a kà á sí.

15. Báwo ni nǹkan ṣe rí fún ilẹ̀ Róòmù ní apá tí ó kẹ́yìn ọ̀rúndún kìíní àti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa?

15 Àwọn tó jọba lẹ́yìn Tìbéríù, tí wọ́n kópa gẹ́gẹ́ bí ọba àríwá, ni Gáyọ́sì Késárì (Kaligúlà), Kíláúdù Kìíní, Nérò, Fẹsipásíà, Títù, Dòmítíà, Néfà, Tírájánì àti Hádíríánì. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Nínú ọ̀ràn tí ó pọ̀ jù lọ, ìlànà ìṣàkóso àti ètò ìkọ́lé tí Ọ̀gọ́sítọ́sì gbé kálẹ̀ ni àwọn tí wọ́n jọba lẹ́yìn rẹ̀ ń bá nìṣó, ṣùgbọ́n wọn kò lo ìdánúṣe bí tirẹ̀, wọ́n sì ṣàṣehàn jù ú lọ.” Ìwé yìí kan náà sọ síwájú sí i pé: “Apá ìkẹyìn ọ̀rúndún kìíní àti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejì ni ògo Róòmù dé òtéńté rẹ̀, ìgbà yẹn ni àwọn ènìyàn rẹ̀ sì pọ̀ jù lọ.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìjàngbọ̀n ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ààlà ilẹ̀ ọba Róòmù lákòókò yẹn, àkọ́kọ́ nínú ìfigagbága tí a sọ tẹ́lẹ̀, láàárín òun àti ọba gúúsù, kò wáyé títí di ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa.

A RU Ú DÌDE SÍ ỌBA GÚÚSÙ

16, 17. (a) Ta ní bọ́ sípò ọba àríwá tí Dáníẹ́lì 11:25 tọ́ka sí? (b) Ta ló wá bọ́ sípò ọba gúúsù, báwo ni èyí sì ṣe wáyé?

16 Áńgẹ́lì Ọlọ́run ń bá àsọtẹ́lẹ̀ náà lọ, pé: “[Ọba àríwá] yóò . . . ru agbára rẹ̀ àti ọkàn-àyà rẹ̀ dìde sí ọba gúúsù pẹ̀lú ẹgbẹ́ ológun ńláǹlà; ọba gúúsù, ní tirẹ̀, yóò sì ru ara rẹ̀ sókè fún ogun pẹ̀lú ẹgbẹ́ ológun kan tí ó pọ̀ lọ́nà tí ó peléke tí ó sì lágbára ńlá. Òun [ọba àríwá] kì yóò sì dúró, nítorí wọn yóò pète-pèrò ní ìlòdìsí i. Àwọn náà gan-an tí ń jẹ oúnjẹ adùnyùngbà rẹ̀ ni yóò sì fa ìwópalẹ̀ rẹ̀. Àti ní ti ẹgbẹ́ ológun rẹ̀, ìkún omi yóò gbé e lọ, ọ̀pọ̀ yóò sì ṣubú sílẹ̀ ní òkú.”—Dáníẹ́lì 11:25, 26.

17 Ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún ọdún lẹ́yìn tí Ọkitéfíà sọ Íjíbítì di ara ìgbèríko Róòmù, Olú Ọba Ọrélíà ti Róòmù bọ́ sójú ọpọ́n gẹ́gẹ́ bí ọba àríwá. Ní àkókò náà, Ọbabìnrin Sẹtimíà Senobíà ti ìlú Pálímírà tí ó jẹ́ ẹkùn ilẹ̀ Róòmù ni ó wà ní ipò ọba gúúsù. * (Wo “Senobíà—Jagunjagun Ọbabìnrin Ìlú Pálímírà,” lójú ìwé 252.) Àwọn ọmọ ogun Pálímírà lọ gba Íjíbítì ní ọdún 269 Sànmánì Tiwa ní dídọ́gbọ́n sọ pé ṣe ni àwọn fẹ́ rí i dájú pé kò kúrò lábẹ́ Róòmù. Ṣe ni Senobíà sì fẹ́ sọ Pálímírà di olórí àwọn ìlú ìlà oòrùn, ó fẹ́ máa ṣàkóso àwọn ìgbèríko ilẹ̀ Róòmù tí wọ́n wà ní ìhà ìlà oòrùn. Bí Ọrélíà ṣe gbọ́ ohun tí Senobíà fẹ́ dáwọ́ lé ló bá “ru agbára rẹ̀ àti ọkàn-àyà rẹ̀ dìde” láti lọ gbéjà ko Senobíà.

18. Kí ni àbájáde gídígbò tó wáyé láàárín Olú Ọba Ọrélíà, tó jẹ́ ọba àríwá, àti Ọbabìnrin Senobíà, tó jẹ́ ọba gúúsù?

18 Ọba gúúsù, ìyẹn ìṣàkóso tí Senobíà ṣolórí rẹ̀, “ru ara rẹ̀ sókè” láti bá ọba àríwá ja ogun ní lílo “ẹgbẹ́ ológun kan tí ó pọ̀ lọ́nà tí ó peléke tí ó sì lágbára ńlá” lábẹ́ ọ̀gágun méjì, Sábídásì àti Sábáì. Àmọ́, Ọrélíà gba Íjíbítì, ó sì wá gbógun lọ sí Éṣíà Kékeré àti Síríà. Émésà (tí ń jẹ́ Homs báyìí) ni a ti ṣẹ́gun Senobíà, tí ó fi sá padà sí ìlú Pálímírà. Nígbà tí Ọrélíà sàga ti ìlú yẹn, Senobíà ṣe bẹbẹ láti gbà á sílẹ̀ ṣùgbọ́n kò ṣàṣeyọrí. Òun àti ọmọ rẹ̀ bá fẹsẹ̀ fẹ lọ sí apá Páṣíà, ṣùgbọ́n àwọn ará Róòmù gbá wọn mú ní Odò Yúfírétì. Àwọn ará Pálímírà wá jọ̀wọ́ ìlú wọn lọ́dún 272 Sànmánì Tiwa. Ọrélíà dá Senobíà sí, òun ni ó sì gba àfiyèsí jù lọ nígbà tí ó yan ìyan aṣẹ́gun la ìlú Róòmù já lọ́dún 274 Sànmánì Tiwa. Senobíà wá di ìyàwó ilé ní Róòmù títí dọjọ́ ikú rẹ̀.

19. Báwo ni Ọrélíà ṣe ṣubú nítorí ‘ìpète-pèrò tí wọ́n ṣe lòdì sí i’?

19 Ọrélíà alára ‘kò dúró, nítorí wọ́n pète pèrò ní ìlòdìsí i.’ Lọ́dún 275 Sànmánì Tiwa, ó gbéra láti lọ gbógun ja àwọn ará Páṣíà. Bí ó ṣe ń dúró ní Tírésì de ìgbà tí àǹfààní máa ṣí sílẹ̀ fún un láti gba ìwọdò sọdá sí Éṣíà Kékeré, ni àwọn tí wọ́n ‘ń jẹ oúnjẹ rẹ̀’ bá pète pèrò sí i, wọ́n sì fa “ìwópalẹ̀” rẹ̀. Ńṣe ni ó fẹ́ jẹ Ẹ́rọ́sì akọ̀wé rẹ̀ níyà fún ṣíṣe ségesège. Ṣùgbọ́n, Ẹ́rọ́sì lọ fi èké kọ orúkọ àwọn òṣìṣẹ́ ọba kan gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a fẹ́ pa. Bí àwọn òṣìṣẹ́ ọba wọ̀nyí ṣe rí orúkọ wọ̀nyí, ni wọ́n bá dìtẹ̀, wọ́n sì pa Ọrélíà.

20. Báwo ni “ẹgbẹ́ ológun” ọba àríwá ṣe di èyí tí ‘ìkún omi gbé lọ’?

20 Ikú Olú Ọba Ọrélíà kò mú kí ìgbòkègbodò ọba àríwá dópin. Àwọn ọba Róòmù yòókù ń bá a nìṣó. Fún àkókò kan, olú ọba ìwọ̀ oòrùn wà, olú ọba ìlà oòrùn sì wà lẹ́ẹ̀kan náà ní ilẹ̀ ọba Róòmù. Lábẹ́ àwọn wọ̀nyí ni “ẹgbẹ́ ológun” ọba àríwá ti di èyí tí ‘ìkún omi gbé lọ,’ tàbí “tí a fọ́n ká,” * ọ̀pọ̀ sì “ṣubú sílẹ̀ ní òkú” nípasẹ̀ àwọn ogun tí àwọn ẹ̀yà Jámánì níhà àríwá ń gbé jà wọ́n. Àwọn ẹ̀yà Goth ya wọ ààlà ilẹ̀ àwọn ará Róòmù ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa. A wá ń bá a lọ láti gbógun ja ilẹ̀ Róòmù léraléra. Lọ́dún 476 Sànmánì Tiwa, Odoásà, aṣáájú àwọn ará Jámánì, rọ olú ọba tí ó kẹ́yìn nínú àwọn tí ń ṣàkóso láti Róòmù lóyè. Nígbà tí ó fi máa di ọ̀rúndún kẹfà, a ti fọ́ Ilẹ̀ Ọba Róòmù níhà ìwọ̀ oòrùn yángá, àwọn ọba Jámánì wá ń ṣàkóso ilẹ̀ Britannia, Gaul, Ítálì, Àríwá Áfíríkà, àti Sípéènì. Apá ìlà oòrùn ilẹ̀ ọba Róòmù wà títí di ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún.

A PÍN ILẸ̀ ỌBA ŃLÁ KAN

21, 22. Àwọn àyípadà wo ni Kọnsitatáìnì ṣe ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa?

21 Áńgẹ́lì Jèhófà kò wulẹ̀ mẹ́nu kan àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí kò pọndandan ní ti bí Ilẹ̀ Ọba Róòmù ṣe fọ́ sí wẹ́wẹ́, èyí tí ó gbà tó ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ńṣe ló bọ́ sórí àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ọba àríwá àti ọba gúúsù yóò ṣe pitú síwájú sí i. Àmọ́ ṣá, bí a bá ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó ṣẹlẹ̀ nínú Ilẹ̀ Ọba Róòmù yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dá ọba méjèèjì tí ń figẹ̀ wọngẹ̀ náà mọ̀ nígbà ìkẹyìn.

22 Ní ọ̀rúndún kẹrin, Olú Ọba Kọnsitatáìnì ti Róòmù sọ pé Ìjọba tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn Kristẹni apẹ̀yìndà. Lọ́dún 325 Sànmánì Tiwa, ó tilẹ̀ pe ìpàdé ìgbìmọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì sí ìlú Níséà ní Éṣíà Kékeré, ó sì fúnra rẹ̀ ṣe alága níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, Kọnsitatáìnì gbé ààfin ọba kúrò ní ìlú Róòmù lọ sí Baisáńtíọ́mù, tàbí Kọnsitantinópù, ó sì sọ ìlú yẹn di olú ìlú rẹ̀ tuntun. Olú ọba kan ṣoṣo ní ń ṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Róòmù títí di ìgbà tí Olú Ọba Tìódósọ́sì Kìíní kú ní January 17, ọdún 395 Sànmánì Tiwa.

23. (a) Báwo ni a ṣe wá pín Ilẹ̀ Ọba Róòmù lẹ́yìn ikú Tìódósọ́sì? (b) Ìgbà wo ni Ilẹ̀ Ọba Ìlà Oòrùn dópin? (d) Ta ni ó ń ṣàkóso Íjíbítì ní nǹkan bí ọdún 1517?

23 Lẹ́yìn ikú Tìódósọ́sì, àwọn ọmọ rẹ̀ pín Ilẹ̀ Ọba Róòmù mọ́ra wọn lọ́wọ́. Apá ìwọ̀ oòrùn bọ́ sí Hónórọ́sì lọ́wọ́, ìlà oòrùn sì jẹ́ ti Akádíọ́sì, ó sì fi Kọnsitantinópù ṣe olú ìlú rẹ̀. Ilẹ̀ Britannia, Gaul, Ítálì, Sípéènì àti Àríwá Áfíríkà wà lára àwọn ìgbèríko apá ti ìwọ̀ oòrùn. Makedóníà, Tírésì, Éṣíà Kékeré, Síríà àti Íjíbítì jẹ́ ìgbèríko apá ti ìlà oòrùn. Alẹkisáńdíríà olú ìlú ilẹ̀ Íjíbítì bọ́ sọ́wọ́ àwọn Sarasẹ́nì (Árábù) lọ́dún 642 Sànmánì Tiwa, Íjíbítì sì di ìgbèríko abẹ́ àwọn alákòóso tí ó jẹ́ Mùsùlùmí. Ní January ọdún 1449, Kọnsitatáìnì Kọkànlá di olú ọba ìkẹyìn ní apá ìlà oòrùn. Àwọn Ọ́tómánì ilẹ̀ Turkey tí Sultan Mehmed Kejì ń darí, gba Kọnsitantinópù ní May 29, 1453, èyí sì fòpin sí Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti Ìlà Oòrùn. Ní ọdún 1517, Íjíbítì di ìgbèríko ilẹ̀ Turkey. Àmọ́, láìpẹ́, ilẹ̀ ọba gúúsù àtijọ́ yìí wá bọ́ sí abẹ́ ilẹ̀ ọba mìíràn láti ìhà ìwọ̀ oòrùn.

24, 25. (a) Gẹ́gẹ́ bí àwọn òpìtàn kan ṣe sọ, kí ní jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́? (b) Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn sí ipò “olú ọba” ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́?

24 Bíṣọ́ọ̀bù ẹ̀sìn Kátólíìkì ní Róòmù, ní pàtàkì, Póòpù Leo Kìíní, tí òkìkí rẹ̀ kàn pé ó lo ọlá àṣẹ póòpù ní ọ̀rúndún karùn-ún Sànmánì Tiwa, yọrí ní apá ìwọ̀ oòrùn Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Bí àkókò ti ń lọ, póòpù fi àdábọwọ́ ara rẹ̀ lọ dé olú ọba apá ìwọ̀ oòrùn ládé. Èyí wáyé ní ìlú Róòmù lọ́jọ́ Kérésìmesì ti ọdún 800 Sànmánì Tiwa, nígbà tí Póòpù Leo Kẹta dé Ọba Charles (Charlemagne) ti ẹ̀yà Franks ní Jámánì ládé gẹ́gẹ́ bí olú ọba Ilẹ̀ Ọba Róòmù tuntun ti Ìwọ̀ Oòrùn. Ọba tí a fi jẹ yìí ni olú ọba jíjẹ tún fi bẹ̀rẹ̀ ní Róòmù, gẹ́gẹ́ bí àwọn òpìtàn sì ṣe sọ, ìyẹn ni ìbẹ̀rẹ̀ Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́. Láti ìgbà náà ni Ilẹ̀ Ọba Ìlà Oòrùn àti Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ ní ìwọ̀ oòrùn ti wà, tí àwọn méjèèjì sì ń sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni.

25 Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn arọ́pò Charlemagne di ọba tí kò gbéṣẹ́. Kódà, kò sí olú ọba ní ìgbà kan. Láàárín àkókò náà, Otto Kìíní, ọba Jámánì, ti gba àkóso ọ̀pọ̀ ibi níhà àríwá àti àárín gbùngbùn Ítálì. Ó kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Ítálì. Ní February 2, ọdún 962 Sànmánì Tiwa, Póòpù John Kejìlá dé Otto Kìíní ládé gẹ́gẹ́ bí olú ọba Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́. Jámánì ni olú ìlú rẹ̀ wà, ará Jámánì sì ni àwọn olú ọba rẹ̀, gan-an bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ọba rẹ̀ ṣe jẹ́. Ní ọ̀rúndún márùn-ún lẹ́yìn náà, ipò “olú ọba” wá di ti ìdílé Hapsburg láti ilẹ̀ Austria, àwọn ló sì jẹ ẹ́ fún èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú ìyókù ọdún tí Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ fi wà.

ỌBA MÉJÈÈJÌ TÚN WÁ SÓJÚ TÁYÉ LẸ́Ẹ̀KAN SÍ I

26. (a) Kí ni a lè sọ nípa òpin Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́? (b) Ta ló di ọba àríwá?

26 Napoléon Kìíní ṣẹ́ Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ léegun ẹ̀yìn nígbà tó ní òun ò gbà pé ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ wà, èyí jẹ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìṣẹ́gun rẹ̀ ní ilẹ̀ Jámánì nínú ọdún 1805. Bí Olú Ọba Francis Kejì kò ti lè dáàbò bo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Róòmù, ó fi ipò yẹn sílẹ̀ ní August 6, 1806, ó sì padà lọ bójú tó ìjọba orílẹ̀-èdè tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú ọba ilẹ̀ Austria. Lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún ó lé mẹ́fà, Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́—tí póòpù Kátólíìkì ti Róòmù kan, Leo Kẹta, àti Charlemagne, ọba láti ẹ̀yà Franks, dá sílẹ̀—dópin. Lọ́dún 1870, Róòmù di olú ìlú ìjọba Ítálì, tí ó gbòmìnira kúrò lábẹ́ ìlú Fátíkàn. Lọ́dún tí ó tẹ̀ lé e, ilẹ̀ ọba ti Jámánì bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí a ti sọ Wilhelm Kìíní ní késárì, tàbí kaiser. Bí ọba àríwá òde òní—Jámánì—ṣe wá sójú táyé nìyẹn.

27. (a) Báwo ni Íjíbítì ṣe di orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ àṣẹ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì? (b) Ta ló bọ́ sí ipò ọba gúúsù?

27 Ṣùgbọ́n kí ni a fi dá ọba gúúsù òde òní mọ̀? Ìtàn fi hàn pé Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gba agbára ọba ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún. Bí Napoléon Kìíní ṣe fẹ́ ṣèdíwọ́ fún àwọn ọ̀nà tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń gbà ṣòwò, ó lọ ṣẹ́gun Íjíbítì lọ́dún 1798. Ogun bá bẹ̀rẹ̀, àpapọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ti àwọn Ọ́tómánì fipá mú kí ará Faransé yìí kúrò ní Íjíbítì, èyí tí a mọ̀ sí ọba gúúsù ní ìbẹ̀rẹ̀ gídígbò yìí. Nínú ọ̀rúndún tí ó tẹ̀ lé e, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì túbọ̀ ń nípa lórí Íjíbítì. Lẹ́yìn ọdún 1882, Íjíbítì wá di orílẹ̀-èdè tí ó gbára lé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pátápátá. Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 1914, abẹ́ ilẹ̀ Turkey ni Íjíbítì wà, tí aṣojú ọba tàbí ajẹ́lẹ̀ sì ń ṣàkóso rẹ̀. Àmọ́, lẹ́yìn tí ilẹ̀ Turkey ti gbè sẹ́yìn ilẹ̀ Jámánì nínú ogun yẹn, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì bá rọ aṣojú ọba tí ó wà ní Íjíbítì lóyè, ó sì sọ pé Íjíbítì di orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ Gẹ̀ẹ́sì. Bí àjọṣe ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe túbọ̀ ń wọra sí i, wọ́n wá di Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Àwọn méjèèjì ló pa pọ̀ bọ́ sí ipò ọba gúúsù.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 17 Níwọ̀n bí orúkọ náà “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” ti jẹ́ orúkọ oyè, ó lè tọ́ka sí ohunkóhun tí ó bá ń ṣàkóso títí kan ọba, ọbabìnrin tàbí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó para pọ̀.

^ ìpínrọ̀ 20 Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé Dáníẹ́lì 11:26 nínú Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures—With References, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

KÍ LO LÓYE?

• Olú Ọba Róòmù wo ló kọ́kọ́ dìde gẹ́gẹ́ bí ọba àríwá, ìgbà wo ni ó sì rán “afipámúni” jáde?

• Ta ló bọ́ sípò ọba àríwá lẹ́yìn Ọ̀gọ́sítọ́sì, báwo ni a sì ṣe “ṣẹ́ Aṣáájú májẹ̀mú náà”?

• Kí ni àbájáde gídígbò tó wáyé láàárín Ọrélíà ọba àríwá àti Senobíà ọba gúúsù?

• Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí Ilẹ̀ Ọba Róòmù, àwọn agbára wo sì ni wọ́n bọ́ sípò ọba méjèèjì ní apá òpin ọ̀rúndún kọkàndínlógún?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 248 sí 251]

A BỌLÁ FÚN Ọ̀KAN, A TẸ́ŃBẸ́LÚ ÌKEJÌ

Ọ̀KAN sọ orílẹ̀-èdè oníjọba àjùmọ̀ṣe tí gbọ́nmisi omi-òto kún fọ́fọ́ di ilẹ̀ ọba àgbáyé. Ìkejì mú ọrọ̀ ibẹ̀ pọ̀ sí i ní ìlọ́po ogún láàárín ọdún mẹ́tàlélógún. A bọlá fún ọ̀kan nígbà tí ó kú, ṣùgbọ́n a tẹ́ńbẹ́lú ìkejì. Ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù nasẹ̀ láti inú ìṣàkóso ọ̀kan nínú olú ọba Róòmù yìí bọ́ sí ti ìkejì. Ta ni wọ́n? Èé sì ti ṣe tí a fi bọlá fún ọ̀kan tí a kò sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìkejì?

‘BÍRÍKÌ NI Ó BÁ ÌLÚ RÓÒMÙ, MÁBÌLÌ NI Ó SỌ Ọ́ DÀ’

Nígbà tí wọ́n ṣìkà pa Júlíọ́sì Késárì ní ọdún 44 ṣááju Sànmánì Tiwa, Gáyọ́sì Ọkitéfíà ọmọ ọmọ arábìnrin rẹ̀ jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún péré. Kíá ni Ọkitéfíà ọ̀dọ́ gbéra lọ sí Róòmù láti gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ nítorí Júlíọ́sì Késárì ti gbà á ṣọmọ, ó sì ti sọ ọ́ di olórí àrólé ara rẹ̀. Ó bá alátakò tó le kú pàdé níbẹ̀, ìyẹn ni Máàkù Áńtónì, tí ó jẹ́ olórí aṣojú Késárì, ẹni tí ó rò pé òun ni olórí àrólé. Nítorí èyí, ọdún mẹ́tàlá ni wọ́n fi jùmọ̀ du ipò tí wọ́n sì ń pa ètekéte lọ́nà ti ìṣèlú.

Kìkì ìgbà tí Ọkitéfíà ṣẹ́gun àpapọ̀ agbo ọmọ ogun Ọbabìnrin Kilẹopátírà ti Íjíbítì àti Máàkù Áńtónì àlè rẹ̀ (lọ́dún 31 ṣááju Sànmánì Tiwa) ni Ọkitéfíà tó di alákòóso Ilẹ̀ Ọba Róòmù láìsí àtakò. Lọ́dún tí ó tẹ̀ lé e, Áńtónì àti Kilẹopátírà fọwọ́ ara wọn para wọn, Ọkitéfíà bá sọ ilẹ̀ Íjíbítì di tirẹ̀. Bí a ṣe mú ìràlẹ̀rálẹ̀ Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì kúrò nìyẹn, tí Róòmù sì di agbára ayé.

Bí Ọkitéfíà ṣe rántí pé àṣìlò agbára ló mú kí wọ́n ṣìkà pa Júlíọ́sì Késárì, ó ṣọ́ra kí ó má bàa ṣe àṣìṣe kan náà. Ó dọ́gbọ́n gbé agọ̀ ìjọba àjùmọ̀ṣe wọ ìjọba àdáṣe tí ó ń ṣe kí ó má bàa ṣẹ àwọn ará Róòmù tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìjọba àjùmọ̀ṣe. Kò gbà kí wọ́n pe òun ní “ọba” tàbí “apàṣẹwàá.” Ó tẹ̀ síwájú sí i ní kíkéde pé òun fẹ́ gbé àkóso gbogbo àwọn ìgbèríko lé Ilé Aṣòfin Àgbà ní Róòmù lọ́wọ́, ó sì sọ pé òun fẹ́ fi àwọn ipò tí òun wà sílẹ̀. Ọgbọ́n tó ta yìí jẹ wọ́n. Bí Ilé Aṣòfin Àgbà tí jẹ́ onímọrírì, wọ́n rọ Ọkitéfíà pé kí ó ṣì wà ní àwọn ipò rẹ̀, kí ó sì máa bá àkóso rẹ̀ nìṣó lórí àwọn ìgbèríko kan.

Ní àfikún sí i, ní January 16, ọdún 27 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ilé Aṣòfin Àgbà fún Ọkitéfíà ní oyè “Ọ̀gọ́sítọ́sì,” tí ó túmọ̀ sí “Ẹni Tí A Gbé Ga, Ẹni Ọ̀wọ̀.” Yàtọ̀ sí pé Ọkitéfíà tẹ́wọ́ gba oyè náà, ó tún yí orúkọ oṣù kan padà sí orúkọ ara rẹ̀, ó sì yá ọjọ́ kan láti inú oṣù February kún ti August, kí ó lè ní iye ọjọ́ kan náà pẹ̀lú oṣù July, tí a fi orúkọ Júlíọ́sì Késárì sọ. Bí Ọkitéfíà ṣe di olú ọba àkọ́kọ́ tí Róòmù ní nìyẹn, tí a sì wá mọ̀ ọ́n sí Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì tàbí “Ẹni Ọlọ́lá.” Lẹ́yìn náà, ó tún jẹ oyè “pontifex maximus” (baba awo), ní ọdún 2 ṣááju Sànmánì Tiwa—ọdún tí a bí Jésù—Ilé Aṣòfin Àgbà fi joyè Pater Patriae, “Baba Orílẹ̀-Èdè Rẹ̀.”

Lọ́dún kan náà yẹn, “àṣẹ àgbékalẹ̀ kan jáde lọ láti ọ̀dọ̀ Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì pé kí gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé forúkọ sílẹ̀; . . . gbogbo ènìyàn sì ń rin ìrìn àjò lọ láti forúkọ sílẹ̀, olúkúlùkù sí ìlú ńlá tirẹ̀.” (Lúùkù 2:1-3) Nítorí àṣẹ yìí, a bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì.—Dáníẹ́lì 11:20; Míkà 5:2.

Ìwà àìlábòsí wà dé ìwọ̀n kan lábẹ́ ìjọba Ọ̀gọ́sítọ́sì, owó wọn sì níye lórí gan-an. Ọ̀gọ́sítọ́sì sì tún dá ètò ìfìwéránṣẹ́ tí ó já fáfá sílẹ̀, ó ṣe àwọn ọ̀nà àti afárá. Ó ṣe àtúntò ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ó dá ẹgbẹ́ ọmọ ogun ojú omi tí yóò máa wà lọ títí sílẹ̀, ó sì dá agbo ẹ̀ṣọ́ alágbára tí a mọ̀ sí Ẹ̀ṣọ́ Ọba sílẹ̀. (Fílípì 1:13) Òun ni àwọn òǹkọ̀wé bíi Fágílì àti Hórásì fi ṣe aláfẹ̀yìntì tí wọ́n fi gòkè àgbà, tí àwọn oníṣẹ́ ọnà sì ń fi iṣẹ́ ọnà dá onírúurú àrà ẹlẹ́wà, tí a wá ń pè ní ìṣọnà àwọn ará Róòmù àtijọ́. Ọ̀gọ́sítọ́sì parí àwọn ilé tí Júlíọ́sì Késárì kò lè kọ́ parí, ó sì tún ọ̀pọ̀lọpọ̀ tẹ́ńpìlì ṣe. Ètò Pax Romana (“Àlàáfíà Róòmù”) tí ó dá sílẹ̀ wà fún ohun tí ó ju igba ọdún lọ. Ọ̀gọ́sítọ́sì kú ní August 19, ọdún 14 Sànmánì Tiwa, lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin, a sì sọ ọ́ di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ lẹ́yìn náà.

Ọ̀gọ́sítọ́sì yangàn pé ‘bíríkì ni òun bá Róòmù, òun sì sọ ọ́ di mábìlì.’ Níwọ̀n bí kò ti fẹ́ kí Róòmù tún padà sínú ayé gbọ́nmisi omi-òto ti ìgbà àkóso àjùmọ̀ṣe àtẹ̀yìnwá, ó fẹ́ dá olú ọba tí yóò jẹ tẹ̀ lé e lẹ́kọ̀ọ́ ṣáájú. Ṣùgbọ́n rírí arọ́pò dìṣòro fún un. Ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kan, àti ọmọ ọmọ rẹ̀ méjì, àti ọkọ ọmọ rẹ̀, àti ọmọ kan tí aya rẹ̀ gbé wá sílé rẹ̀, tí gbogbo wọn jẹ́ ọkùnrin, kú lọ́kọ̀ọ̀kan pátá, tí ó fi wá ku kìkì Tìbéríù, tí ó jẹ́ ọmọ kan tí aya rẹ̀ gbé wá sílé rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí arọ́pò rẹ̀.

“ẸNÌ KAN TÍ A ÓÒ TẸ́ŃBẸ́LÚ”

Kò pé oṣù kan lẹ́yìn ikú Ọ̀gọ́sítọ́sì tí Ilé Aṣòfin Àgbà ní Róòmù fi fi Tìbéríù ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta jẹ olú ọba. Tìbéríù ń bẹ láyé títí di March ọdún 37 Sànmánì Tiwa, ó sì ṣàkóso dìgbà yẹn. Nítorí náà, òun ni olú ọba Róòmù ní gbogbo àkókò tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn.

Àtìwà rere àtìwà burúkú ni Olú Ọba Tìbéríù ní lọ́wọ́. Lára ìwà rere rẹ̀ ni pé kì í fẹ́ náwó nínàákúnàá sórí ohun afẹ́. Nítorí èyí, ilẹ̀ ọba yẹn láásìkí, ó sì rówó ṣèrànwọ́ láti mú kí nǹkan lè padà bọ̀ sípò fún àwọn ènìyàn nígbà àjálù àti tí nǹkan kò bá lọ déédéé. Ibi tí Tìbéríù tún dára sí ni pé, ó ka ara rẹ̀ sí ènìyàn kan náà bí àwọn yòókù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ oyè ló kọ̀ láti gbà, Ọ̀gọ́sítọ́sì ni ó sì sábà máa ń darí ìjọsìn tí a bá fẹ́ fún olú ọba sí dípò ara rẹ̀. Kò fi orúkọ ara rẹ̀ sọ oṣù kankan nínú ọdún bí Ọ̀gọ́sítọ́sì àti Júlíọ́sì Késárì ti ṣe fúnra wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbà kí ẹlòmíràn ṣe bẹ́ẹ̀ fún òun.

Àmọ́ ṣá, ìwà burúkú Tìbéríù tayọ ìwà rere rẹ̀. Ìfura àti àgàbàgebè rẹ̀ ti pọ̀ jù nínú bí ó ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn lò, ènìyàn rẹpẹtẹ ni a sì fàṣẹ ọba gbé lọ pa nígbà ìṣàkóso rẹ̀ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí sì wà nínú àwọn wọ̀nyí. Ó fẹ òfin lèse-majesté (ọ̀tẹ̀ sí ìjọba) lójú débi pé, ní àfikún sí ọ̀tẹ̀ dídì, ó tún kan ọ̀rọ̀ àbùkù sí òun fúnra rẹ̀. Bóyá òfin yìí ni àwọn Júù lò láti fi fínná mọ́ Pọ́ńtíù Pílátù, Gómìnà ará Róòmù náà, láti pa Jésù.—Jòhánù 19:12-16.

Tìbéríù mú kí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Ẹ̀ṣọ́ Ọba wà lẹ́bàá ìlú Róòmù nípa kíkọ́ àwọn àgọ́ olódi fún wọn níhà àríwá odi ìlú náà. Wíwà tí àwọn Ẹ̀ṣọ́ náà wà níbẹ̀ ń kó ìpayà bá Ilé Aṣòfin Àgbà ní Róòmù, èyí tí ó jẹ́ ìdènà fún Tìbéríù ní ti bí ó ṣe ń lo agbára rẹ̀, ó sì mú kí ó lè paná rògbòdìyàn láwùjọ. Bákan náà, Tìbéríù fún ìwà ìfinisùn níṣìírí, ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ gbáà sì ni apá ìkẹyìn ìṣàkóso rẹ̀ dà.

Nígbà tí Tìbéríù fi máa kú, òǹrorò ẹ̀dá ni a kà á sí. Ṣe ni àwọn ará Róòmù yọ̀ nígbà tí ó kú, Ilé Aṣòfin Àgbà sì kọ̀ láti sọ ọ́ di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. Nítorí ìdí wọ̀nyí àti àwọn mìíràn, a rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ tí a sọ pé “ẹnì kan tí a óò tẹ́ńbẹ́lú” yóò dìde gẹ́gẹ́ bí “ọba àríwá,” ṣẹ sí Tìbéríù lára.—Dáníẹ́lì 11:15, 21.

KÍ LO LÓYE?

• Báwo ni Ọkitéfíà ṣe di olú ọba àkọ́kọ́ ní Róòmù?

• Kí ni a lè sọ nípa àwọn ohun tí ìjọba Ọ̀gọ́sítọ́sì gbé ṣe?

• Ìwà rere àti ìwà burúkú wo ni Tìbéríù hù?

• Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ ní ti “ẹnì kan tí a óò tẹ́ńbẹ́lú” ṣe ṣẹ sí Tìbéríù lára?

[Àwòrán]

Tìbéríù

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 252 sí 255]

SENOBÍÀ—JAGUNJAGUN ỌBABÌNRIN ÌLÚ PÁLÍMÍRÀ

“OBÌNRIN náà kò fi bẹ́ẹ̀ mọ́ra . . . Eyín rẹ̀ funfun kinniwin, ẹyinjú rẹ̀ dúdú, tí ó rí roboto bí òṣùpá, mọ́lẹ̀ roro, àkànṣe ẹwà fífanimọ́ra tí ó ní sì buyì kún un. Ohùn rẹ̀ rinlẹ̀, ó sì dùn létí. Òye ìwé tó ní mú kí jíjẹ́ tí ó jẹ́ obìnrin bí ọkùnrin túbọ̀ mú hánhán kí ó sì dára sí i. Ó gbọ́ èdè Látìn, bẹ́ẹ̀ ni èdè Gíríìkì, èdè Síríákì àti èdè Íjíbítì sì yọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu dọ́ba.” Báyìí ni òpìtàn náà, Edward Gibbon, ṣe gbóríyìn fún Senobíà—jagunjagun ọbabìnrin ìlú Pálímírà ti ilẹ̀ Síríà.

Ọkọ Senobíà ni Odaenátọ́sì, ọ̀tọ̀kùlú kan ní ìlú Pálímírà, tí a fi oyè aṣojú ìjọba ilẹ̀ Róòmù dá lọ́lá lọ́dún 258 Sànmánì Tiwa nítorí pé ó ṣàṣeyọrí nínú ogun tí ó gbé ja ilẹ̀ Páṣíà ní tìtorí Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, Galiénọ́sì olú ọba Róòmù fún Odaenátọ́sì ní oyè corrector totius Orientis (gómìnà gbogbo Ìlà Oòrùn). Èyí jẹ́ ní ìmọrírì fún bí ó ṣe ṣẹ́gun Ọba Ṣápúrì Kìíní ti Páṣíà. Nígbà tí ó yá, Odaenátọ́sì wá fún ara rẹ̀ ní oyè “ọba àwọn ọba.” Ìgboyà àti òye Senobíà ni a lè sọ pé ó jẹ́ ìdí pàtàkì tí Odaenátọ́sì fi ṣe àwọn àṣeyọrí wọ̀nyí.

SENOBÍÀ FẸ́ LÁTI DÁ ILẸ̀ ỌBA KAN SÍLẸ̀

Lọ́dún 267 Sànmánì Tiwa, nígbà tí àṣeyọrí Odaenátọ́sì dé òtéńté rẹ̀, wọ́n ṣìkà pa òun àti àrólé rẹ̀. Ni Senobíà bá gbapò ọkọ rẹ̀ nítorí pé ọmọkùnrin tí Senobíà bí ṣì kéré. Bí ó ti jẹ́ arẹwà, tí ó fẹ́ràn ká gbé nǹkan ribiribi ṣe, alábòójútó tí ó já fáfá, tí ó ti mọ́ lára láti máa bá ọkọ rẹ̀ jagun kiri, tí èdè mélòó kan sì yọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, àwọn ènìyàn ìjọba rẹ̀ bọ̀wọ̀ fún un bákan ṣáá, wọ́n sì tì í lẹ́yìn. Senobíà fẹ́ràn ẹ̀kọ́ kíkọ́, àwọn ìjìmì ni ó sì fi yí ara rẹ̀ ká. Ọ̀kan lára àwọn alábàádámọ̀ràn rẹ̀ ni Kásọ́sì Lọ́ńgínọ́sì, ọlọ́gbọ́n èrò orí àti sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́—a sọ pé “ó jẹ́ igi ìwé àti àká ìmọ̀.” Nínú ìwé Palmyra and Its Empire—Zenobia’s Revolt Against Rome (Pálímírà àti Ilẹ̀ Ọba Rẹ̀—Ìṣọ̀tẹ̀ Senobíà sí Ilẹ̀ Róòmù), òǹṣèwé Richard Stoneman sọ pé: “Láàárín ọdún márùn-ún lẹ́yìn ikú Odaenátọ́sì . . . , Senobíà ti jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ gbà pé òun ni ìyálóde Ìlà Oòrùn.”

Ilẹ̀ Páṣíà, tí Senobíà àti ọkọ rẹ̀ ti sọ di aláìlágbára, ní ń bẹ ní ìhà kan ilẹ̀ àkóso rẹ̀, ilẹ̀ Róòmù tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ fọ́ ni ó sì wà níhà kejì. Òpìtàn náà, J. M. Roberts, sọ nípa bí ipò nǹkan ṣe rí ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù nígbà náà pé: “Ọ̀rúndún kẹta jẹ́ . . . àkókò tí ilẹ̀ Róòmù kòṣòro gidigidi ní ààlà ilẹ̀ rẹ̀ ti ìhà ìlà oòrùn àti ti ìwọ̀ oòrùn pẹ̀lú, nínú Róòmù pàápàá, ogun abẹ́lé ti bẹ̀rẹ̀, ìjà nítorí ipò ọba sì ń wáyé lemọ́lemọ́ bí àwọn ọba ṣe ń kú léraléra. Ọba méjìlélógún (yàtọ̀ sí àwọn afèrújọba) ló jẹ tẹ̀léra tẹ̀léra.” Ṣùgbọ́n ní ti ìyálóde Síríà, òun nìkan ṣoṣo ni ọba aláṣẹ ní ilẹ̀ ọba rẹ̀, mìmì kankan kò sì mì í. Stoneman sọ pé: “Bí ilẹ̀ ọba méjì [ti Páṣíà àti ti Róòmù] ṣe wà níkàáwọ́ rẹ̀, ó rọrùn pé kí obìnrin náà fẹ́ láti dá ìkẹta sílẹ̀, èyí tí yóò kúkú máa ṣàkóso méjèèjì pa pọ̀.”

Àǹfààní ṣí sílẹ̀ fún Senobíà láti mú kí ìṣàkóso rẹ̀ gbòòrò sí i lọ́dún 269 Sànmánì Tiwa nígbà tí afèrújọba kan tí ń du ipò ọba ní Róòmù yọjú sí Íjíbítì. Kíá ni àwọn ọmọ ogun Senobíà gbéra lọ sí Íjíbítì, wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà pátápátá, wọ́n sì sọ orílẹ̀-èdè náà di tiwọn. Bí ó ṣe kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọbabìnrin ilẹ̀ Íjíbítì, ló bá fi orúkọ ara rẹ̀ ṣe àwọn owó ẹyọ jáde. Ìjọba rẹ̀ wá gbòòrò láti odò Náílì dé odò Yúfírétì wàyí. Ìgbà yìí gan-an nínú ìgbésí ayé Senobíà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ sípò “ọba gúúsù.”—Dáníẹ́lì 11:25, 26.

IBI TÍ SENOBÍÀ FI ṢE OLÚ ÌLÚ

Senobíà mú kí Pálímírà, tí ó fi ṣe olú ìlú, túbọ̀ lágbára, ó sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ débi pé òun àti àwọn ìlú ńlá ilẹ̀ Róòmù jọ wà ní ipò kan náà. A díwọ̀n àwọn olùgbé ibẹ̀ pé wọ́n ju ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ [150,000] lọ. Àwọn ilé tí ó wà fún ará ìlú, àwọn tẹ́ńpìlì, ọgbà, òpó, ohun ìrántí, tí wọ́n jojú ní gbèsè ni wọ́n kún ìlú Pálímírà, ìlú kan tí a mọ odi tí a sọ pé ó gùn tó kìlómítà mọ́kànlélógún yí ká. Àwọn ìloro tí ó ní òpó ọ̀ṣọ́ rìbìtì rìbìtì, tí gíga wọn ju mítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún—tí iye wọn jẹ́ nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ—ni wọ́n ṣe sí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ òpópónà pàtàkì pàtàkì. Ère àwọn akọni àti àwọn ọlọ́rọ̀ tí ó jẹ́ olóore, tí a gbẹ́ lódindi tàbí láti igbá-àyà sókè, pọ̀ rẹpẹtẹ nínú ìlú yẹn. Ní ọdún 271 Sànmánì Tiwa, Senobíà gbé ère ìrántí ti ara rẹ̀ àti ti ọkọ rẹ̀ olóògbé kalẹ̀.

Tẹ́ńpìlì Oòrùn jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí a kọ́ dáradára jù lọ ní ìlú Pálímírà, ó sì dájú pé òun ló gba iwájú nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn ìlú náà. Ọlọ́run àjúbàfún kan tí ó sopọ̀ mọ́ ọlọ́run oòrùn ni ó ṣeé ṣe kí Senobíà alára máa jọ́sìn. Àmọ́, ilẹ̀ onírúurú ẹ̀sìn ni Síríà jẹ́ ní ọ̀rúndún kẹta. Àwọn ẹlẹ́sìn tó sọ pé Kristẹni làwọn, àwọn ẹlẹ́sìn Júù, àti àwọn olùjọsìn oòrùn àti òṣùpá, wà nínú ilẹ̀ ọba Senobíà. Kí ni ìṣarasíhùwà obìnrin yìí sí onírúurú ọ̀nà ìgbà-jọ́sìn wọ̀nyí? Òǹkọ̀wé náà, Stoneman, sọ pé: “Olùṣàkóso tí ó bá gbọ́n kò ní ṣàìka àwọn àṣà èyíkéyìí tí ó bá dà bí ẹni pé ó báamu lójú àwọn ènìyàn rẹ̀ sí. . . . Wọ́n . . . ń rò ó pé, ńṣe ni a kó àwọn ọlọ́run jọ pọ̀ síbẹ̀ fún àtìlẹyìn àwọn ará Pálímírà.” Dájúdájú, Senobíà kò janpata lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn.

Ànímọ́ fífanimọ́ra tí Senobíà ní mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fẹ́ràn rẹ̀. Ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni ipa tí ó kó ní ti dídúró fún ọba tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì. Àmọ́, ìṣàkóso rẹ̀ kò ju ọdún márùn-ún lọ. Ọrélíà ọba Róòmù ṣẹ́gun Senobíà lọ́dún 272 Sànmánì Tiwa, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ kó ìkógun púpọ̀ ní ìlú Pálímírà tí ìlú náà kò fi tún lè gbérí mọ́. Ọba yìí ṣàánú Senobíà. Wọ́n ní Senobíà wá fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ilé aṣòfin àgbà ní Róòmù, ó sì jọ pé ó tipa báyìí fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ fún ìyóókù ìgbésí ayé rẹ̀.

KÍ LO LÓYE?

• Báwo ni a ṣe ṣàpèjúwe ànímọ́ Senobíà?

• Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ohun tí Senobíà gbé ṣe?

• Kí ni ìṣarasíhùwà Senobíà sí ọ̀ràn ẹ̀sìn?

[Àwòrán]

Ọbabìnrin Senobíà ń bá àwọn sójà rẹ̀ sọ̀rọ̀

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 246]

ÀWỌN ỌBA INÚ DÁNÍẸ́LÌ 11:20-26

Ọba Àríwá Ọba Gúúsù

Dáníẹ́lì 11:20 Ọ̀gọ́sítọ́sì

Dáníẹ́lì 11:21-24 Tìbéríù

Dáníẹ́lì 11:25, 26 Ọrélíà Ọbabìnrin Senobíà

Pípín tí Ilẹ̀ Ọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì,

Ilẹ̀ Ọba Jámánì èyí tí

Róòmù pín gẹ́gẹ́ Agbára Ayé

bí a ṣe sọ tẹ́lẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tẹ̀ léló

fa ìdásílẹ̀

[Àwòrán]

Tìbéríù

[Àwòrán]

Ọrélíà

[Àwòrán]

Ère Charlemagne

[Àwòrán]

Ọ̀gọ́sítọ́sì

[Àwòrán]

Ọkọ̀ ogun ojú omi ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 230]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 233]

Ọ̀gọ́sítọ́sì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 234]

Tìbéríù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 235]

Àṣẹ tí Ọ̀gọ́sítọ́sì pa ló mú kí Jósẹ́fù àti Màríà lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 237]

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀, a “ṣẹ́” Jésù ní ti pé ó kú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 245]

1. Charlemagne 2. Napoléon Kìíní 3. Wilhelm Kìíní 4. Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì, Ogun Àgbáyé Kìíní