Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbàgbọ́ Wọn La Àdánwò Lílekoko Já

Ìgbàgbọ́ Wọn La Àdánwò Lílekoko Já

Orí Karùn-ún

Ìgbàgbọ́ Wọn La Àdánwò Lílekoko Já

1. Kí ni èrò ọ̀pọ̀lọpọ̀ nípa fífi ìfọkànsìn wọn fún Ọlọ́run àti fífi í fún orílẹ̀-èdè wọn?

ỌLỌ́RUN ha ni ó yẹ kí o fọkàn sìn tàbí orílẹ̀-èdè tí o ń gbé inú rẹ̀? Ọ̀pọ̀ yóò dáhùn pé, ‘Àwọn méjèèjì ni mo ń júbà. Mo ń jọ́sìn Ọlọ́run bí ìlànà ẹ̀sìn mi ṣe sọ; lẹ́sẹ̀ kan náà, mo jẹ́jẹ̀ẹ́ ìfọkànsìn fún ìlú ìbílẹ̀ mi.’

2. Báwo ni ọba Bábílónì ṣe jẹ́ òpómúléró nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn àti nínú ìṣèlú?

2 Ààlà ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín ìfọkànsìn lọ́nà ti ẹ̀sìn àti ìfọkànsin orílẹ̀-èdè ẹni lè dà bí pé kò hàn kedere lónìí, ṣùgbọ́n ní Bábílónì ìgbàanì, kò tilẹ̀ sí ìyàtọ̀ rárá. Ní ti gidi, ní ìlú náà, ọ̀ràn ìlú àti ti ẹ̀sìn wé pọ̀ mọ́ra tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn kò fi ṣeé dá mọ̀ yàtọ̀ nígbà mìíràn. Ọ̀jọ̀gbọ́n Charles F. Pfeiffer sọ pé: “Ní Bábílónì ìgbàanì, ọba ni Àlùfáà Àgbà, òun náà sì ni alákòóso ìlú. Òun ni ó ń rú ẹbọ, òun ni ó sì ń pinnu ohun tí àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ máa ṣe ní ti ọ̀ràn ẹ̀sìn.”

3. Kí ní fi hàn pé Nebukadinésárì jẹ́ ẹlẹ́sìn paraku kan?

3 Gbé Nebukadinésárì Ọba yẹ̀ wò. Orúkọ rẹ̀ pàápàá túmọ̀ sí “Kí Nébò, Dáàbò Bo Àrólé!” Nébò ni ọlọ́run ọgbọ́n àti iṣẹ́ àgbẹ̀ ní Bábílónì. Ẹlẹ́sìn paraku ni Nebukadinésárì. Bí a ti ṣe sọ ṣáájú, ó kọ́ àwọn tẹ́ńpìlì, ó sì ṣe àwọn tẹ́ńpìlì lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọlọ́run Bábílónì, ó sì ń fún Mádọ́kì, ẹni tí ó ń gbé ògo àwọn ìṣẹ́gun rẹ̀ fún, ní ìfọkànsìn rẹ̀ ní pàtàkì. * Ó tún dà bí pé Nebukadinésárì gbẹ́kẹ̀ lé iṣẹ́ wíwò gidigidi láti wéwèé àwọn ọ̀nà tí yóò gbà jagun.—Ìsíkíẹ́lì 21:18-23.

4. Ṣàpèjúwe ẹ̀mí ìsìn ní Bábílónì.

4 Ní tòótọ́, ẹ̀mí ìsìn gbòde kan ní gbogbo Bábílónì. Ìlú náà ní ohun tí ó ju àádọ́ta tẹ́ńpìlì, nínú èyí tí wọ́n ti ń jọ́sìn àwọn akọ àti abo ọlọ́run tí ó pọ̀ lọ jàra, títí kan mẹ́talọ́kan tí í ṣe, Anu (ọlọ́run sánmà), Enlil (ọlọ́run ilẹ̀ ayé, afẹ́fẹ́ àti ìjì), àti Ea (ọlọ́run omi). Mẹ́talọ́kan mìíràn tún ní nínú, Sin (ọlọ́run òṣùpá), Shamash (ọlọ́run oòrùn), àti Ishtar (ọlọ́run ìmú-irúmọ jáde). Idán pípa, oṣó àti ìwòràwọ̀ kó ipa pàtàkì nínú ìjọsìn Bábílónì.

5. Ìpèníjà wo ni ipò ọ̀ràn ẹ̀sìn ní Bábílónì jẹ́ fún àwọn Júù tí ó jẹ́ ìgbèkùn?

5 Gbígbé láàárín àwọn ènìyàn tí ń jọ́sìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọlọ́run jẹ́ ìpèníjà gíga gidigidi fún àwọn Júù tí ó jẹ́ ìgbèkùn. Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú, Mósè ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé yóò yọrí sí ohun tí ó burú jáì fún wọn bí wọ́n bá yàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Afúnnilófin Gíga Jù Lọ. Mósè sọ fún wọn pé: “Jèhófà yóò kó ìwọ àti ọba rẹ tí ìwọ yóò gbé kalẹ̀ lórí rẹ lọ sí orílẹ̀-èdè kan tí ìwọ kò mọ̀, yálà ìwọ tàbí àwọn baba ńlá rẹ; ibẹ̀ sì ni ìwọ yóò ti sin àwọn ọlọ́run mìíràn, ti igi àti ti òkúta.”—Diutarónómì 28:15, 36.

6. Èé ṣe tí gbígbé ní Bábílónì fi jẹ́ àkànṣe ìpèníjà fún Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà?

6 Àwọn Júù ti wá bá ara wọn nínú ipò ìṣòro yẹn wàyí. Jíjẹ́ oníwà títọ́ sí Jèhófà yóò ṣòro gan-an ni, pàápàá fún Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà. Ńṣe ni a kanlẹ̀ yan àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ fún ìlò lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba. (Dáníẹ́lì 1:3-5) Rántí pé a tilẹ̀ tún fún wọn lórúkọ àwọn ará Bábílónì—Bẹliteṣásárì, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò—bóyá láti lè mú kí wọ́n di ẹni tí ń gbé ìgbésí ayé ní ìbámu pẹ̀lú àyíká tuntun tí wọ́n wà. * Ipò gíga tí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wà yóò mú kí kíkọ̀ tí wọ́n bá kọ̀ láti jọ́sìn àwọn ọlọ́run ilẹ̀ náà lọ́nàkọnà, di èyí tí ó fara hàn kedere—àní kí ó tún jẹ́ ìṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba.

ÈRE WÚRÀ KAN DI EWU

7. (a) Ṣàpèjúwe ère tí Nebukadinésárì gbé kalẹ̀. (b) Kí ni ète tí ère náà wà fún?

7 Ó hàn gbangba pé ìsapá ti fífún ìṣọ̀kan ilẹ̀ ọba rẹ̀ lókun ni ó jẹ́ kí Nebukadinésárì gbé ère kan kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà. Gíga rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́ (mítà mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà (nǹkan bíi mítà mẹ́ta). * Àwọn kan gbà gbọ́ pé ọwọ̀n, tàbí òpó gìrìwò onígun mẹ́rin aboríṣónṣó kan ṣáá ni. Ó ṣeé ṣe kí ó ní ibi ìgbóhunlé gíga kan, lórí èyí tí wọ́n gbé ère ńlá kan tí ó rí bí ènìyàn sí, bóyá tí ó dúró fún Nebukadinésárì alára, tàbí ọlọ́run náà, Nébò. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun ìrántí gogoro yìí jẹ́ àmì Ilẹ̀ Ọba Bábílónì. Nípa bẹ́ẹ̀, ète rẹ̀ ni pé kí a máa rí i kí a sì máa bọ̀wọ̀ fún un.—Dáníẹ́lì 3:1.

8. (a) Àwọn wo ni a pè wá síbi tí a óò ti ṣí ère yẹn, kí sì ni a ní kí àwọn tí ó wà níbẹ̀ ṣe? (b) Kí ni a sọ pé ìyà ẹni tí ó bá kọ̀ láti tẹrí ba níwájú ère náà yóò jẹ́?

8 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Nebukadinésárì ṣètò fún ayẹyẹ láti fi ṣí i. Ó kó àwọn baálẹ̀, aṣíwájú, gómìnà, agbani-nímọ̀ràn, olùtọ́jú ìṣúra, onídàájọ́, ọlọ́pàá agbófinró àti gbogbo olùṣàbójútó àgbègbè abẹ́ àṣẹ náà jọ. Akéde ọba sì ké jáde pé: “A ń sọ fún yín, ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin àwùjọ orílẹ̀-èdè àti èdè, pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn rẹpẹtẹ, háàpù onígun mẹ́ta, ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín, fèrè alápò awọ àti gbogbo oríṣiríṣi ohun èlò ìkọrin, kí ẹ wólẹ̀, kí ẹ sì jọ́sìn ère wúrà tí Nebukadinésárì Ọba gbé kalẹ̀. Ẹnì yòówù tí kò bá wólẹ̀ kí ó sì jọ́sìn ni a ó sọ ní ìṣẹ́jú yẹn sínú ìléru oníná tí ń jó.”—Dáníẹ́lì 3:2-6.

9. Kí ni ó jọ pé ó jẹ́ ìjẹ́pàtàkì títẹríba níwájú ère tí Nebukadinésárì gbé kalẹ̀?

9 Àwọn kan gbà gbọ́ pé ìgbìyànjú láti fipá mú àwọn Júù juwọ́ sílẹ̀ nínú ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe sí Jèhófà ni ó mú kí Nebukadinésárì ṣètò ayẹyẹ yìí. Ó ṣeé ṣe kí èyí má rí bẹ́ẹ̀, nítorí ó dájú pé kìkì àwọn òṣìṣẹ́ ọba nìkan ni a pè wá síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Nípa báyìí, kìkì àwọn Júù tí ó wà ní àwọn ipò kan lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba nìkan ni wọ́n wà níbẹ̀. Nígbà náà, ó dà bí pé ète títẹríba níwájú ère náà jẹ́ láti fún ẹ̀mí ìfìmọ̀ṣọ̀kan láàárín àwọn olórí lókun. Ọ̀mọ̀wé Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ John F. Walvoord sọ pé: “Lọ́nà kan, pípàtẹ àwọn òṣìṣẹ́ ọba lọ́nà bẹ́ẹ̀ jẹ́ fífi agbára ilẹ̀ ọba Nebukadinésárì hàn lọ́nà ìyangàn àti lọ́nà kejì, ó jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti gbóṣùbà fún àwọn ọlọ́run àjúbàfún tí wọ́n kà sí èyí tí ó mú kí àwọn ìṣẹ́gun wọn ṣeé ṣe.”

ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ JÈHÓFÀ KỌ̀ LÁTI JUWỌ́ SÍLẸ̀

10. Èé ṣe tí kò fi ní ṣòro fún àwọn tí kì í ṣe Júù láti ṣègbọràn sí àṣẹ Nebukadinésárì?

10 Láìka ìfọkànsìn wọn sí onírúurú ọlọ́run ilẹ̀ tiwọn sí, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn tí ó péjọ síwájú ère Nebukadinésárì ni kò ní lọ́ tìkọ̀ láti jọ́sìn rẹ̀ rárá. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa Bíbélì kan ṣàlàyé pé: “Òrìṣà bíbọ ti mọ́ gbogbo wọn lára, pé wọ́n ń jọ́sìn ọlọ́run kan kò dí wọn lọ́wọ́ láti tún júbà òmíràn.” Ó tẹ̀ síwájú pé: “Ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ojú ìwòye tí ó gbòde láàárín àwọn abọ̀rìṣà pé ọ̀pọ̀ ọlọ́run ni ó wà . . . àti pé kì í ṣe ohun àìtọ́ láti júbà ọlọ́run àwọn ènìyàn tàbí orílẹ̀-èdè èyíkéyìí.”

11. Èé ṣe tí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò fi kọ̀ láti tẹrí ba níwájú ère náà?

11 Àmọ́, ọ̀ràn ti àwọn Júù yàtọ̀ pátápátá sí èyí. Jèhófà, Ọlọ́run wọn ti pàṣẹ fún wọn pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ tàbí ìrísí tí ó dà bí ohunkóhun tí ó wà nínú ọ̀run lókè tàbí tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ tàbí tí ó wà nínú omi lábẹ́ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n, nítorí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.” (Ẹ́kísódù 20:4, 5) Nítorí náà, bí ohun orin ṣe bẹ̀rẹ̀ sí dún, tí àwọn tí ó péjọ tẹrí ba níwájú ère náà, àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta—Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò—wà lórí ìdúró.—Dáníẹ́lì 3:7.

12. Ẹ̀sùn kí ni àwọn ará Kálídíà kan fi kan àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, èé sì ti ṣe?

12 Kíkọ̀ tí àwọn Hébérù mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ ọba kọ̀ láti jọ́sìn ère náà mú kí inú àwọn ará Kálídíà kan ru ṣùṣù. Wọ́n tọ ọba lọ lọ́gán, wọ́n sì “fẹ̀sùn kan àwọn Júù.” * Wọn kò fẹ́ gbọ́ àlàyé kankan rárá. Nítorí pé àwọn olùfisùn wọn fẹ́ kí a jẹ àwọn Hébérù náà níyà lórí ẹ̀sùn àìdúróṣinṣin àti ìṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sọ pé: “Àwọn Júù kan wà tí o yàn sípò iṣẹ́ àbójútó lórí àgbègbè abẹ́ àṣẹ Bábílónì, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò; àwọn abarapá ọkùnrin yìí kò fi ọ́ pè rárá, ọba, wọn kò sin àwọn ọlọ́run rẹ, wọn kò sì jọ́sìn ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.”—Dáníẹ́lì 3:8-12.

13, 14. Báwo ni Nebukadinésárì ṣe hùwà padà sí ìgbésẹ̀ tí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò gbé?

13 Ẹ wo irú ìjákulẹ̀ tí yóò ti bá Nebukadinésárì pé àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà kò pa àṣẹ òun mọ́! Ó hàn gbangba pé kò ṣàṣeyọrí láti yí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò padà di ẹni tí ń fi ìdúróṣinṣin ṣe alágbàwí fún Ilẹ̀ Ọba Bábílónì. Òun kò ha ti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ nínú ọgbọ́n àwọn ará Kálídíà? Họ́wù, ó tilẹ̀ ti yí wọn lórúkọ padà pàápàá! Àmọ́, bí Nebukadinésárì bá rò pè ẹ̀kọ́ tí ó pẹtẹrí yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà ìgbàjọ́sìn tuntun tàbí pé yíyí wọn lórúkọ padà yóò yí irú ẹni tí wọ́n jẹ́ padà, àṣìṣe ńlá gbáà ló ṣe. Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò ṣì fi ìdúróṣinṣin jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà.

14 Inú Nebukadinésárì Ọba ru. Lọ́gán, ó ké sí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò. Ó béèrè pé: “Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ṣé bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́ pé ẹ kò sin àwọn ọlọ́run mi, ẹ kò sì jọ́sìn ère wúrà tí mo gbé kalẹ̀?” Láìsí àní-àní, Nebukadinésárì kò gbà á gbọ́, kàyéfì ló fi ń sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Ó ṣe tán, ńṣe ló máa rò ó pé, ‘Báwo ni ọkúnrin mẹ́ta olórí pípé ṣe lè ṣàìka irú àṣẹ tí ó ṣe kedere tó báyìí sí—tí ìyà tí ẹni tí ó bá ṣàìgbọràn yóò jẹ sì le koko tó bẹ́ẹ̀?’—Dáníẹ́lì 3:13, 14.

15, 16. Àǹfààní wo ni Nebukadinésárì nawọ́ rẹ̀ sí àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà?

15 Nebukadinésárì ṣe tán láti fún àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ní àǹfààní mìíràn. Ó sọ pé: “Nísinsìnyí, bí ẹ bá ti múra tán tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn rẹpẹtẹ, háàpù onígun mẹ́ta, ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín, fèrè alápò awọ, gbogbo oríṣiríṣi ohun èlò ìkọrin, ẹ óò wólẹ̀, ẹ ó sì jọ́sìn ère tí mo ṣe, ó dára. Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá jọ́sìn, ní ìṣẹ́jú yẹn a ó sọ yín sínú ìléru oníná tí ń jó. Ta sì ni ọlọ́run yẹn tí ó lè gbà yín sílẹ̀ ní ọwọ́ mi?”—Dáníẹ́lì 3:15.

16 Ní kedere, ẹ̀kọ́ láti inú àlá ère náà (tí a kọ sínú Dáníẹ́lì orí kejì) kò pẹ́ lọ títí nínú èrò inú àti ọkàn-àyà Nebukadinésárì. Bóyá ó tilẹ̀ ti gbàgbé ọ̀rọ̀ tí òun fúnra rẹ̀ sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Ọlọ́run yín jẹ́ Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn ọba.” (Dáníẹ́lì 2:47) Nísinsìnyí, ó dà bí pé Nebukadinésárì ń pe Jèhófà níjà, ní sísọ pé Òun pàápàá kò lè gba àwọn Hébérù náà lọ́wọ́ ìyà tí yóò jẹ wọ́n.

17. Báwo ni Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò ṣe fèsì sí ohun tí ọba nawọ́ rẹ̀ sí wọn?

17 Kò sí ìdí fún Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò láti tún ọ̀ràn náà gbé yẹ̀ wò. Lẹ́sẹ̀ kẹsẹ̀ ni wọ́n dáhùn pé: “Nebukadinésárì, a kò sí lábẹ́ ọ̀ranyàn rárá láti sọ ọ̀rọ̀ kankan padà fún ọ. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run wa, ẹni tí àwa ń sìn lè gbà wá sílẹ̀. Òun yóò gbà wá sílẹ̀ kúrò nínú ìléru oníná tí ń jó àti kúrò ní ọwọ́ rẹ, ọba. Ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó di mímọ̀ fún ọ, ọba, pé àwọn ọlọ́run rẹ kì í ṣe èyí tí àwa ń sìn, àwa kì yóò sì jọ́sìn ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.”—Dáníẹ́lì 3:16-18.

Ó DI INÚ ÌLÉRU ONÍNÁ!

18, 19. Kí ní ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n ju àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sínú ìléru oníná?

18 Bí ìhónú Nebukadinésárì ṣe ru, ó pàṣẹ pé kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mú ìléru náà gbóná sí i nígbà méje ju bí a ti sábà máa ń mú un gbóná. Ó wá pàṣẹ fún “àwọn abarapá ọkùnrin kan tí wọ́n ní ìmí nínú” pé kí wọ́n de Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, kí wọn sì sọ wọ́n sínú “ìléru oníná tí ń jó.” Wọ́n ṣe bí ọba ṣe pa láṣẹ, ní jíju àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sínú iná ní dídè tàwọn ti ẹ̀wù wọn lọ́rùn wọn—bóyá kí wọ́n bàa lè tètè jóná kíákíá. Àmọ́, àwọn dòǹgárì Nebukadinésárì fúnra wọn gan-an ni ọwọ́ iná náà pa.—Dáníẹ́lì 3:19-22.

19 Àmọ́, ohun àràmàǹdà kan ń ṣẹlẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò wà láàárín ìléru oníná, ọwọ́ iná kò jó wọn. Ẹ wo bí kàyéfì Nebukadinésárì ṣe máa pọ̀ tó! Dídè le dan-indan-in ni wọ́n wà nígbà tí a jù wọ́n sínú iná tí ń jó fòfò, ṣùgbọ́n wọ́n ṣì wà láàyè. Họ́wù, fàlàlà ni wọ́n ń rìn kiri nínú iná! Ṣùgbọ́n, Nebukadinésárì tún ṣàkíyèsí ohun mìíràn. Ó béèrè lọ́wọ́ àwọn olóyè rẹ̀ onípò gíga pé: “Àwọn abarapá ọkùnrin mẹ́ta ha kọ́ ni a sọ sí àárín iná ní dídè?” Wọ́n dá ọba lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ọba.” Nebukadinésárì kígbe pé: “Wò ó! Abarapá ọkùnrin mẹ́rin ni mo ń rí tí wọ́n ń rìn káàkiri ní òmìnira ní àárín iná náà, ọṣẹ́ kankan kò sì ṣe wọ́n, ìrísí ẹni kẹrin sì jọ ti ọmọ àwọn ọlọ́run.”—Dáníẹ́lì 3:23-25.

20, 21. (a) Kí ni Nebukadinésárì ṣàkíyèsí nípa Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò nígbà tí wọ́n jáde wá láti inú ìléru? (b) Kí ni Nebukadinésárì gbà tipátipá?

20 Nebukadinésárì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ìléru oníná náà. Ó ké jáde pé: “Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, ẹ jáde síta kí ẹ sì máa bọ̀!” Àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta bá rìn jáde nínú iná náà. Láìsí àní-àní, háà ṣe gbogbo àwọn tí ó rí iṣẹ́ ìyanu yìí—títí kan àwọn baálẹ̀, àwọn aṣíwájú, àwọn gómìnà, àwọn òṣìṣẹ́ onípò gíga. Họ́wù, ṣe ló dà bí pé àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí kò tilẹ̀ tí ì wọnú ìléru náà rí! Òórùn iná kò sí lára wọn, iná kò sì wi ẹyọ kan lára irun orí wọn.—Dáníẹ́lì 3:26, 27.

21 Tipátipá, Nebukadinésárì Ọba wá gbà wàyí, pé Jèhófà ni Ọlọ́run Gíga Jù Lọ. Ó polongo pé: “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, tí ó rán áńgẹ́lì rẹ̀, tí ó sì gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e sílẹ̀, tí wọ́n sì yí ọ̀rọ̀ ọba pàápàá padà, tí wọ́n sì jọ̀wọ́ ara wọn, nítorí pé wọn kò sìn, wọn kò sì jọ́sìn ọlọ́run èyíkéyìí rárá bí kò ṣe Ọlọ́run tiwọn.” Ọba wá fi ìkìlọ̀ lílekoko yìí kún un pé: “Láti ọ̀dọ̀ mi sì ni àṣẹ ìtọ́ni kan ti jáde, pé ènìyàn, àwùjọ orílẹ̀-èdè tàbí èdè èyíkéyìí tí ó bá sọ ohun tí kò tọ́ sí Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, a óò gé e sí wẹ́wẹ́, a ó sì sọ ilé rẹ̀ di ilé ìgbọ̀nsẹ̀ gbogbo ènìyàn; níwọ̀n bí kò ti sí ọlọ́run mìíràn tí ó lè dáni nídè bí èyí.” Pẹ̀lú ìyẹn, a dá àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta padà sí ipò ojú rere ọba, wọ́n sì “láásìkí ní àgbègbè abẹ́ àṣẹ Bábílónì.”—Dáníẹ́lì 3:28-30.

ÌGBÀGBỌ́ ÀTI ÀDÁNWÒ LÍLEKOKO NÁÀ LÓNÌÍ

22. Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní ṣe dojú kọ ipò tí ó jọ ti Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò?

22 Lónìí, àwọn olùjọsìn Jèhófà dojú kọ irú ipò tí ó jọ ti Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò. Lóòótọ́, àwọn ènìyàn Ọlọ́run lè máà sí nígbèkùn ní ti gidi. Síbẹ̀, Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun ‘kò ní jẹ́ apá kan ayé.’ (Jòhánù 17:14) Wọ́n jẹ́ “ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” ní ti pé wọn kò tẹ́wọ́ gba àwọn àṣà, ìṣarasíhùwà àti ìṣesí tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ti àwọn ènìyàn tí ó yí wọn ká. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe kọ̀wé, àwọn Kristẹni ní láti “jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí.”—Róòmù 12:2.

23. Báwo ni àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe mú ìdúró gbọn-in gbọn-in, báwo sì ni àwọn Kristẹni lónìí ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn?

23 Àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kọ̀ láti dáṣà bí ti ètò àwọn nǹkan ti Bábílónì. Kódà, ìtọ́ni tí a fún wọn jinlẹ̀jinlẹ̀ nínú ọgbọ́n àwọn ará Kálídíà kò mì wọ́n pínkín. Ipò wọn ní ti ọ̀ràn ẹ̀sìn kì í ṣe èyí tí a ń dúnàádúrà rẹ̀, Jèhófà sì ni wọ́n fún ní ìfọkànsìn wọn. Bí àwọn Kristẹni tòní náà ṣe ní láti dúró gbọn-in gbọn-in nìyẹn. Kò sí ìdí fún wọn láti tijú nítorí pé wọ́n yàtọ̀ sí àwọn tí ń bẹ nínú ayé. Ní tòótọ́, “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (1 Jòhánù 2:17) Nítorí náà, yóò jẹ́ ìwà òmùgọ̀ àti ìmúlẹ̀mófo láti mú ara ẹni bá ètò àwọn nǹkan tí ń kú lọ yìí mu.

24. Kí ni ìjọra tí ó wà nínú irú ìdúró tí àwọn Kristẹni tòótọ́ mú àti ti àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà?

24 Àwọn Kristẹni ní láti ṣọra fún onírúurú ìbọ̀rìṣà gbogbo, títí kan irú àwọn tí ó jẹ́ lọ́nà àrékérekè. * (1 Jòhánù 5:21) Ní ṣíṣègbọràn, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò dúró lọ́nà ọ̀wọ̀ níwájú ère wúrà náà, ṣùgbọ́n wọ́n mọ̀ pé títẹríba níwájú rẹ̀ ti ré kọjá ìfaraṣàpèjúwe ìbọ̀wọ̀fúnni lásán. Ó jẹ́ ìṣe ìjọsìn, bí wọ́n bá sì lọ́wọ́ nínú rẹ̀, wọn yóò forí fá ìrunú Jèhófà. (Diutarónómì 5:8-10) John F. Walvoord kọ̀wé pé: “Kíkí àsíá ni ó jásí, àmọ́, nítorí bí ìdúróṣinṣin lọ́nà ti ẹ̀sìn ṣe wọnú ìdúróṣinṣin sí orílẹ̀-èdè, ó ṣeé ṣe kí ó ní ọ̀ràn ìsìn nínú.” Lónìí, irú ìdúró gbọn-in gbọn-in bẹ́ẹ̀ ni àwọn Kristẹni tòótọ́ mú lòdì sí ìbọ̀rìṣà.

25. Ẹ̀kọ́ wo ni o ti rí kọ́ nínú ìtàn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi nínú ìgbésí ayé Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò?

25 Àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò pèsè ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n gidi, tí ó tayọ, fún gbogbo àwọn tí ó bá pinnu láti fún Jèhófà ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe. Ó dájú pé àwọn Hébérù mẹ́ta wọ̀nyí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ nípa ọ̀pọ̀ tí ó lo ìgbàgbọ́, títí kan àwọn tí “wọ́n dá ipá iná dúró.” (Hébérù 11:33, 34) Jèhófà yóò san èrè fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Ó gba àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta là kúrò nínú ìléru oníná tí ń jó náà, ṣùgbọ́n ó dá wa lójú pé yóò jí gbogbo àwọn adúróṣinṣin rẹ̀ tí ó pàdánù ìwàláàyè wọn gẹ́gẹ́ bí olùpa ìwà títọ́ mọ́ dìde, yóò sì fi ìyè ayérayé jíǹkí wọn. Ọ̀nà yòówù kí ó jẹ́ nínú méjèèjì, Jèhófà “ń ṣọ́ ọkàn àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀; ó ń dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.”—Sáàmù 97:10.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 3 Àwọn kan gbà gbọ́ pé Mádọ́kì, tí wọ́n kà sí olùdásílẹ̀ Ilẹ̀ Ọba Bábílónì, dúró fún Nímírọ́dù tí wọ́n ti sọ di àkúnlẹ̀bọ. Ṣùgbọ́n, a kò lè fi ìdánilójú sọ èyí.

^ ìpínrọ̀ 6 “Bẹliteṣásárì” túmọ̀ sí “Dáàbò Bo Ìwàláàyè Ọba.” Ó ṣeé ṣe kí “Ṣádírákì” túmọ̀ sí “Àṣẹ Aku,” ọlọ́run òṣùpá ti àwọn ará Sumer. Ó dà bí pé Méṣákì tọ́ka sí ọlọ́run àwọn ará Sumer, Àbẹ́dínígò sì túmọ̀ sí “Ìránṣẹ́ Négò,” tàbí Nébò.

^ ìpínrọ̀ 7 Ní ríro ti gìrìwò ère yìí, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú Bíbélì kan gbà gbọ́ pé igi ni wọ́n fi ṣe é kí wọ́n tó fi wúrà bò ó.

^ ìpínrọ̀ 12 Ọ̀rọ̀ Árámáìkì tí a túmọ̀ sí “fẹ̀sùn kàn” túmọ̀ sí láti ‘jẹ’ ẹnì kan ‘tèérún-tèérún’ tàbí lédè mìíràn láti jẹ ẹni náà tán poo, nípasẹ̀ ìfọ̀rọ̀-èké-banijẹ́.

^ ìpínrọ̀ 24 Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì so àjẹkì àti ojúkòkòrò pọ̀ mọ́ ìbọ̀rìṣà.—Fílípì 3:18, 19; Kólósè 3:5.

KÍ LO LÓYE?

• Èé ṣe tí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò fi kọ̀ láti tẹrí ba níwájú ère tí Nebukadinésárì gbé kalẹ̀?

• Báwo ni Nebukadinésárì ṣe hùwà padà sí ìdúró tí àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta mú?

• Báwo ni Jèhófà ṣe san èrè fún àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fún ìgbàgbọ́ wọn?

• Kí ni o ti rí kọ́ láti inú kíkíyè sí ìtàn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi nínú ìgbésí ayé Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 68]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 70]

1. Tẹ́ńpìlì onílé gogoro ti Bábílónì (ó jẹ́ ipele-ipele àgbékà aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀)

2. Tẹ́ńpìlì Mádọ́kì

3. Wàláà idẹ nínú èyí tí ọlọ́run Mádọ́kì (apá òsì) àti Nébò (apá ọ̀tún) ti dúró sórí dírágónì

4. Ohun ọ̀ṣọ́ tí a gbẹ́ àwòrán Nebukadinésárì sí, ẹni tí òkìkí rẹ̀ kàn ní ti àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé tí ó ṣe

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 76]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 78]