Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọba Méjèèjì tó Wọ Gídígbò ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Òpin Wọn

Ọba Méjèèjì tó Wọ Gídígbò ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Òpin Wọn

Orí Kẹrìndínlógún

Ọba Méjèèjì tó Wọ Gídígbò ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Òpin Wọn

1, 2. Báwo ni ẹni tí a mọ̀ sí ọba àríwá ṣe yí padà lẹ́yìn ogun àgbáyé kejì?

Bí alexis de Tocqueville, ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n èrò orí àti òpìtàn, ṣe gbé ipò ìṣèlú Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àti ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà yẹ̀ wò, ó kọ̀wé lọ́dún 1835 pé: “Òmìnira ni ohun èlò pàtàkì tí ọ̀kan ń lò láti fi gbé ìgbésẹ̀; èkejì ń lo ìmúnisìn. Ọ̀nà ìgbàṣe-nǹkan . . . wọn yàtọ̀ síra; àmọ́, ṣe ló dà bí pé Adánitán fi ìhùmọ̀ ìkọ̀kọ̀ kan ké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lọ́jọ́ kan tí ó sì gbé kádàrá ìdajì ayé lé olúkúlùkù wọn lọ́wọ́.” Kí ni àwítẹ́lẹ̀ yìí já sí lójú àbájáde Ogun Àgbáyé Kejì? Òpìtàn J. M. Roberts kọ̀wé pé: “Ní òpin Ogun Àgbáyé Kejì, ó dà bí pé ó ṣeé ṣe pé oríṣi ètò agbára ńlá méjì tí ó yàtọ̀ síra lọ́pọ̀lọpọ̀ ni yóò jọba lé ayé lórí, ọ̀kan fìdí kalẹ̀ síbi tó ń jẹ́ Rọ́ṣíà látẹ̀yìnwá, ọ̀kan sì wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.”

2 Nígbà ogun àgbáyé méjèèjì, ilẹ̀ Jámánì ni ó jẹ́ olórí ọ̀tá ọba gúúsù—Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà—òun ni ó sì wà nípò ọba àríwá. Àmọ́, lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, orílẹ̀-èdè yẹn pín sí méjì. Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì di alájọṣepọ̀ ọba gúúsù, Ìlà Oòrùn sì fara mọ́ ìṣàkóso mìíràn tóun náà jẹ́ alágbára—àwùjọ orílẹ̀-èdè oníjọba Kọ́múníìsì tí ilẹ̀ Soviet Union jẹ́ olórí wọn. Àwùjọ orílẹ̀-èdè tàbí ìṣàkóso yìí, dìde gẹ́gẹ́ bí ọba àríwá, ó sì dojú ìjà kíkankíkan kọ àjọṣepọ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Ìfigẹ̀wọngẹ̀ àwọn ọba méjèèjì yìí sì di Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀, tí ó wà láti ọdún 1948 títí dé 1989. Níṣàájú, ọba àríwá ti ilẹ̀ Jámánì ti gbé ìgbésẹ̀ “lòdì sí májẹ̀mú mímọ́.” (Dáníẹ́lì 11:28, 30) Báwo ni àwùjọ orílẹ̀-èdè oníjọba Kọ́múníìsì yóò ṣe hùwà sí májẹ̀mú náà?

ÀWỌN KRISTẸNI TÒÓTỌ́ KỌSẸ̀ ṢÙGBỌ́N WỌ́N BORÍ

3, 4. Àwọn wo ni “àwọn tí ń ṣe ohun burúkú sí májẹ̀mú náà,” àjọṣepọ̀ wo ni wọ́n sì ní pẹ̀lú ọba àríwá?

3 Áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ pé: “Àwọn tí ń ṣe ohun burúkú sí májẹ̀mú náà ni òun [ọba àríwá] yóò sì ṣamọ̀nà sí ìpẹ̀yìndà nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in.” Áńgẹ́lì náà fi kún un pé: “Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ Ọlọ́run wọn, wọn yóò borí, wọn yóò sì gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́. Àti ní ti àwọn tí wọ́n ní ìjìnlẹ̀ òye nínú àwọn ènìyàn náà, wọn yóò la ọ̀pọ̀ lóye. Dájúdájú, a óò mú wọn kọsẹ̀ nípa idà àti ọwọ́ iná, nípa oko òǹdè àti ìpiyẹ́, fún ọjọ́ mélòó kan.”—Dáníẹ́lì 11:32, 33.

4 Kìkì àwọn aṣáájú Kirisẹ́ńdọ̀mù, tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni ṣùgbọ́n tí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ń ba orúkọ Kristẹni gan-an jẹ́, nìkan ni ó lè jẹ́ “àwọn tí ń ṣe ohun burúkú sí májẹ̀mú náà.” Walter Kolarz sọ nínú ìwé rẹ̀ Religion in the Soviet Union, (Ẹ̀sìn ní Ilẹ̀ Soviet Union) pé: “[Nígbà ogun àgbáyé kejì], Ìjọba ilẹ̀ Soviet sapá láti rí i pé àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì fi ohun ìní àti ìṣesí wọn ṣètìlẹyìn fún ìgbèjà ilẹ̀ baba wọn.” Lẹ́yìn ogun náà, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ṣì gbìyànjú láti máa bá ìbádọ́rẹ̀ẹ́ náà lọ láìka ìlànà àìgbà-pọ́lọ́run-wà tí agbára tí ó wá di ọba àríwá báyìí ń tẹ̀ lé sí. Nípa báyìí, Kirisẹ́ńdọ̀mù túbọ̀ di apá kan ayé yìí ju tìgbàkigbà rí lọ—èyí jẹ́ ìpẹ̀yìndà akóninírìíra lójú Jèhófà.—Jòhánù 17:16; Jákọ́bù 4:4.

5, 6. Àwọn wo ni “àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ Ọlọ́run wọn,” kí ni nǹkan sì ti rí fún wọn lábẹ́ ọba àríwá?

5 Àwọn Kristẹni tòótọ́ ńkọ́, ìyẹn, “àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ Ọlọ́run wọn,” àti “àwọn tí wọ́n ní ìjìnlẹ̀ òye”? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni tí ń gbé lábẹ́ àkóso ọba àríwá “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga,” wọn kì í ṣe apá kan ayé yìí. (Róòmù 13:1; Jòhánù 18:36) Bí wọ́n ṣe ń rí i dájú pé àwọn ń san “àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì,” lẹ́sẹ̀ kan náà wọ́n ń fi “àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Mátíù 22:21) Tìtorí èyí, a pe ìwà títọ́ wọn níjà.—2 Tímótì 3:12.

6 Nítorí èyí, àwọn Kristẹni tòótọ́ “kọsẹ̀” wọ́n sì tún “borí” bákan náà. Wọ́n kọsẹ̀ ní ti pé a ṣe inúnibíni lílekoko sí wọn, tí a tilẹ̀ pa àwọn mìíràn. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣẹ́gun ní ti pé ọ̀pọ̀ yanturu wọn dúró gbọn-in gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́. Wọ́n ṣẹ́gun ayé gan-an bí Jésù ti ṣe. (Jòhánù 16:33) Ní àfikún sí i, wọn kò dáwọ́ wíwàásù dúró rárá, kódà bí a bá tilẹ̀ jù wọ́n sẹ́wọ̀n tàbí sí ọgbà ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Nípa ṣíṣe èyí, wọ́n “la ọ̀pọ̀ lóye.” Láìka inúnibíni ní ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ilẹ̀ tí ọba àríwá ń ṣàkóso sí, iye Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pọ̀ sí i. Nítorí ìṣòtítọ́ “àwọn tí wọ́n ní ìjìnlẹ̀ òye,” “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí wọ́n túbọ̀ ń pọ̀ sí i níye, ti jáde wá ní àwọn ilẹ̀ wọ̀nyẹn.—Ìṣípayá 7:9-14.

A YỌ́ ÀWỌN ÈNÌYÀN JÈHÓFÀ MỌ́

7. “Ìrànlọ́wọ́ díẹ̀” wo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí ń gbé lábẹ́ àkóso ọba àríwá rí gbà?

7 Áńgẹ́lì náà sọ pé: “Nígbà tí a bá mú wọn [àwọn ènìyàn Ọlọ́run] kọsẹ̀, a ó fi ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́.” (Dáníẹ́lì 11:34a) Bíborí tí ọba gúúsù borí nínú ogun àgbáyé kejì mú kí ìtura díẹ̀ bá àwọn Kristẹni tí ń gbé ní abẹ́ àkóso ọba tí ń bá a figẹ̀ wọngẹ̀. (Fi wé Ìṣípayá 12:15, 16.) Bákan náà, àwọn tí arọ́pò ọba yìí ṣe inúnibíni sí ń rí ìtura lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bí Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ ṣe ń rọlẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ti wá rí i pé àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ kì í ṣe eléwu ènìyàn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ń gbà wọ́n láàyè lábẹ́ òfin. Ìrànlọ́wọ́ sì tún dé nípasẹ̀ àwọn ogunlọ́gọ̀ tí ń pọ̀ sí i, tí wọ́n ṣègbọràn sí iṣẹ́ wíwàásù láìdáwọ́dúró tí àwọn ẹni àmì òróró ń ṣe, tí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́.—Mátíù 25:34-40.

8. Báwo ni àwọn kan ṣe dára pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run nípasẹ̀ “ìpọ́nni dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in”?

8 Kì í ṣe gbogbo àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn ń fẹ́ láti sin Ọlọ́run láàárín àwọn ọdún tí Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ ń lọ lọ́wọ́ ló fi ọkàn rere ṣe bẹ́ẹ̀. Áńgẹ́lì náà ti kìlọ̀ tẹ́lẹ̀ pé: “Dájúdájú, ọ̀pọ̀ yóò dara pọ̀ mọ́ wọn nípasẹ̀ ìpọ́nni dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in.” (Dáníẹ́lì 11:34b) Àwọn púpọ̀ ni wọ́n fìfẹ́ hàn sí òtítọ́ ṣùgbọ́n tí wọn kò ṣe tán láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Síbẹ̀ náà, àwọn kan tó dà bí pé wọ́n tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà jẹ́ amí fún àwọn aláṣẹ ní ti gidi. Ìròyìn láti orílẹ̀-èdè kan kà pé: “Díẹ̀ nínú àwọn èèyàn kéèyàn wọ̀nyí jẹ́ ara àwọn Kọ́múníìsì paraku tí wọ́n yọ́ wọnú ètò àjọ Olúwa, tí wọ́n fi ìtara ńlá hàn, tí a tilẹ̀ ti yàn wọ́n sí àwọn ipò ẹrù iṣẹ́ gíga pẹ̀lú.”

9. Èé ṣe tí Jèhófà fi gbà kí àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ kan “kọsẹ̀” nítorí àwọn tí wọ́n yọ́ wọlé?

9 Áńgẹ́lì náà ń bá a lọ pé: “A ó sì mú lára àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye kọsẹ̀, láti lè ṣe iṣẹ́ ìyọ́mọ́ nítorí wọn àti láti lè ṣe ìwẹ̀nùmọ́ àti láti lè ṣe ìsọdi-funfun, títí di àkókò òpin; nítorí pé ó ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀.” (Dáníẹ́lì 11:35) Àwọn tí wọ́n yọ́ wọlé wọ̀nyí mú kí àwọn olùṣòtítọ́ kan bọ́ sí ọwọ́ àwọn aláṣẹ. Jèhófà gbà kí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ láti lè ṣe iṣẹ́ ìyọ́mọ́ àti ìwẹ̀nùmọ́ lára àwọn ènìyàn rẹ̀. Gẹ́lẹ́ bí Jésù ṣe “kọ́ ìgbọràn láti inú àwọn ohun tí ó jìyà rẹ̀,” bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn olùṣòtítọ́ wọ̀nyí ṣe kọ́ ìfaradà láti inú dídán tí a dán ìgbàgbọ́ wọn wò. (Hébérù 5:8; Jákọ́bù 1:2, 3; fi wé Málákì 3:3.) Bí a ṣe ‘yọ́ wọn mọ́, tí a wẹ̀ wọ́n mọ́, tí a sì sọ wọ́n di funfun’ nìyẹn.

10. Kí ni gbólóhùn náà “títí di àkókò òpin” túmọ̀ sí?

10 Ìkọ̀sẹ̀ àti ìyọ́mọ́ yóò máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn Jèhófà “títí di àkókò òpin.” Dájúdájú, wọ́n retí pé a óò máa ṣe inúnibíni sí wọn títí tí ètò nǹkan ìsinsìnyí yóò fi dópin. Àmọ́, ọ̀rọ̀ inú èdè Árámáíkì tí ó bá ohun tí a túmọ̀ sí “títí di” níhìn-ín mú gẹ́lẹ́, fara hàn nínú ọ̀rọ̀ Dáníẹ́lì 7:25 lédè Árámáíkì, ohun tí ó sì túmọ̀ sí níbẹ̀ ni “láàárín” tàbí “fún.” Nítorí náà, ní Dáníẹ́lì 11:35, “àkókò òpin” ti ní láti so pọ̀ mọ́ òpin àkókò tí a nílò kí àwọn ènìyàn Ọlọ́run fi di ẹni tí a yọ́ mọ́ bí wọ́n ṣe ń fara da ìkọlù láti ọwọ́ ọba àríwá. Ó dájú pé ìkọ̀sẹ̀ náà dópin ní “àkókò” tí Jèhófà “yàn kalẹ̀.”

ỌBA NÁÀ GBÉ ARA RẸ̀ GA

11. Kí ni áńgẹ́lì náà sọ nípa ìṣarasíhùwà ọba àríwá sí ipò ọba aláṣẹ Jèhófà?

11 Ní ti ọba àríwá, áńgẹ́lì náà fi kún un pé: “Ọba náà yóò sì ṣe bí ìfẹ́ rẹ̀ ní ti gidi, yóò sì gbé ara rẹ̀ ga, yóò sì gbé ara rẹ̀ ga lọ́lá ju gbogbo ọlọ́run lọ; [ní kíkọ̀ láti tẹ́wọ́ gba ipò ọba aláṣẹ Jèhófà] yóò sì sọ àwọn ohun ìyanu lòdì sí Ọlọ́run àwọn ọlọ́run. Dájúdájú, yóò kẹ́sẹ járí títí ìdálẹ́bi náà yóò fi wá sí òpin; nítorí ohun tí a ti ṣe ìpinnu lé lórí ni a gbọ́dọ̀ ṣe. Kò sì ní náání Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀; ìfẹ́-ọkàn fún obìnrin àti gbogbo ọlọ́run mìíràn ni kì yóò sì náání, ṣùgbọ́n yóò gbé ara rẹ̀ ga lọ́lá lórí ẹni gbogbo.”—Dáníẹ́lì 11:36, 37.

12, 13. (a) Ọ̀nà wo ni ọba àríwá gbà kọ “Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀”? (b) Àwọn wo ni àwọn “obìnrin” tí ọba àríwá kò náání “ìfẹ́-ọkàn” wọn? (d) Ta ni “ọlọ́run” tí ọba àríwá fògo fún?

12 Ọba àríwá mú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ṣẹ, ó kọ “Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀,” irú bí Ọlọ́run Mẹ́talọ́kan ti Kirisẹ́ńdọ̀mù sílẹ̀. Ẹ̀kọ́ àìgbà-pọ́lọ́run-wà ni àwùjọ orílẹ̀-èdè oníjọba Kọ́múníìsì lódindi ń gbé lárugẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, ọba àríwá sọ ara rẹ̀ di ọlọ́run, ‘ní gbígbé ara rẹ̀ ga lọ́lá lórí ẹni gbogbo.’ Bí kò ti náání “ìfẹ́-ọkàn fún obìnrin”—àwọn dọ̀bọ̀sìyẹsà ilẹ̀, irú bí orílẹ̀-èdè Àríwá Vietnam, tí ìjọba rẹ̀ ń lò gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́bìnrin—ọba yìí ń ṣe “bí ìfẹ́ rẹ̀.”

13 Bí áńgẹ́lì náà ṣe ń bá àsọtẹ́lẹ̀ náà lọ, ó ní: “Ní ipò rẹ̀, yóò fi ògo fún ọlọ́run odi agbára; àti ọlọ́run tí àwọn baba rẹ̀ kò mọ̀ ni òun yóò fi ògo fún nípasẹ̀ wúrà àti nípasẹ̀ fàdákà àti nípasẹ̀ òkúta iyebíye àti nípasẹ̀ àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra.” (Dáníẹ́lì 11:38) Lóòótọ́, ohun tí ọba àríwá gbẹ́kẹ̀ lé ni fífi ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní kó ohun ìjà ogun jọ, “ọlọ́run odi agbára.” Ipasẹ̀ “ọlọ́run” yìí ni ó ti ń wá ìgbàlà, ó sì ń fi ọrọ̀ ńláǹlà rúbọ lórí pẹpẹ rẹ̀.

14. Báwo ni ọba àríwá ṣe “gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́”?

14 “Òun yóò . . . gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́ lòdì sí àwọn ibi odi agbára tí a dáàbò bò jù lọ, pa pọ̀ pẹ̀lú ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè. Ẹnì yòówù tí ó bá fún un ní àkànṣe àfiyèsí ni òun yóò mú pọ̀ gidigidi ní ògo, ní ti gidi, òun yóò sì mú wọn ṣàkóso láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀; yóò sì pín ilẹ̀ fún iye owó kan.” (Dáníẹ́lì 11:39) Nípa pé ọba àríwá gbẹ́kẹ̀ lé “ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè” ológun tó ní, ó gbé ìgbésẹ̀ “lọ́nà gbígbéṣẹ́” jù lọ, ní ti pé ó fi hàn pé òun jẹ́ àkòtagìrì alágbára ogun “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1) Àwọn tí wọ́n bá fara mọ́ èròǹgbà rẹ̀, ni ó máa ń fi ìtìlẹyìn lọ́nà ìṣèlú, ọrọ̀ ajé, àti nígbà mìíràn, ti ológun san èrè fún.

‘TÍTA KÀN-Ǹ-GBỌ̀N’ NÍ ÀKÓKÒ ÒPIN

15. Báwo ni ọba gúúsù ṣe bá ọba àríwá “ta kàn-ǹ-gbọ̀n”?

15 Áńgẹ́lì náà wí fún Dáníẹ́lì pé: “Ní àkókò òpin, ọba gúúsù yóò bá a ta kàn-ǹ-gbọ̀n.” (Dáníẹ́lì 11:40a) Ọba gúúsù ha ti bá ọba àríwá “ta kàn-ǹ-gbọ̀n” nígbà “àkókò òpin” bí? (Dáníẹ́lì 12:4, 9) Ó ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Dájúdájú àdéhùn àlàáfíà ìfìyàjẹni tí a gbé ka ọba àríwá ìgbà náà—ilẹ̀ Jámánì—lórí jẹ́ ‘ìtakàn-ǹ-gbọ̀n’ kan, títọ́jà láti lè gbẹ̀san. Lẹ́yìn tí ọba gúúsù ṣẹ́gun nínú ogun àgbáyé kejì, ó dojú àwọn ohun ìjà ogun àtọ́míìkì ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ kọ ẹni tí ń bá a figẹ̀ wọngẹ̀ yìí, ó sì tìtorí tirẹ̀ lọ dá ẹgbẹ́ apawọ́pọ̀jagun tí ó lágbára sílẹ̀, ìyẹn, àjọ North Atlantic Treaty Organization (NATO). Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan sọ nípa iṣẹ́ NATO pé: “Ó jẹ́ olórí ohun èlò láti fi ‘kápá’ ilẹ̀ USSR, tí a ti wá kà sí olórí ewu sí àlàáfíà ilẹ̀ Yúróòpù. Ogójì ọdún ni ó fi ṣe iṣẹ́ tí a rán an, ó sì ṣe é láṣeyọrí dájúdájú.” Bí àwọn ọdún Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ ṣe ń bá a lọ, ‘títa kàn-ǹ-gbọ̀n’ ọba gúúsù tún kan lílo ọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ gíga láti máa fi fimú fínlẹ̀ àti ìgbéjàkoni lọ́nà ti ìṣèlú àti ti ológun.

16. Báwo ni ọba àríwá ṣe hùwà nípa bí ọba gúúsù ṣe ń bá a ta kàn-ǹ-gbọ̀n?

16 Báwo ni ọba àríwá ṣe hùwà sí èyí? “Ọba àríwá yóò . . . fipá rọ́lù ú pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọkọ̀ òkun; yóò sì wọ ilẹ̀ náà, yóò ya lù ú, yóò sì là á kọjá.” (Dáníẹ́lì 11:40b) Ìtàn àwọn ọjọ́ ìkẹyìn fi mímú tí ọba àríwá ń mú ààlà rẹ̀ gbòòrò sí i hàn. Nígbà ogun àgbáyé kejì, “ọba” àwọn Násì ya lu àwọn ààlà rẹ̀, ó sì ré e kọjá wọnú àwọn ilẹ̀ tí ó yí i ká. Nígbà tí ogun náà parí, “ọba” tí ó rọ́pò rẹ̀ gbé ilẹ̀ ọba alágbára kan ró. Ní ìgbà Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀, ọba àríwá bá ọ̀tá rẹ̀ yìí jà nínú àwọn ogun tí tọ̀tún tòsì wọn ti pọ̀n sẹ́yìn àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bára wọn jà àti nípa pípọ̀n sẹ́yìn àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ ní ilẹ̀ Áfíríkà, Éṣíà, àti ní Látìn Amẹ́ríkà. Ó ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni tòótọ́, ní ṣíṣèdíwọ́ fún ìgbòkègbodò wọn—àmọ́ ṣá, kò lè dá a dúró lọ́nà kọnà. Gbígbé tí ó ń gbéjà koni lọ́nà ti ológun àti ti ìṣèlú sì mú kí àwọn ilẹ̀ mélòó kan bọ́ sí abẹ́ àkóso rẹ̀. Ohun tí áńgẹ́lì náà sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn, pé: “Ní ti gidi, yóò wọ ilẹ̀ Ìṣelóge [ipò tẹ̀mí tí àwọn ènìyàn Jèhófà wà] pẹ̀lú, a ó sì mú ọ̀pọ̀ ilẹ̀ kọsẹ̀.”—Dáníẹ́lì 11:41a.

17. Ibo ni ìlànà mímú ààlà gbòòrò sí i tí ọba àríwá ń tẹ̀ lé dé dúró?

17 Síbẹ̀síbẹ̀, ọwọ́ ọba àríwá kò tẹ ìṣẹ́gun àgbáyé. Áńgẹ́lì náà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ìwọ̀nyí ni àwọn tí yóò sá àsálà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, Édómù àti Móábù àti lájorí lára àwọn ọmọ Ámónì.” (Dáníẹ́lì 11:41b) Ní ayé ìgbàanì, agbedeméjì ààlà ilẹ̀ ọba gúúsù ti Íjíbítì àti ilẹ̀ ọba àríwá ti Síríà ni ilẹ̀ Édómù, Móábù àti Ámónì wà. Lóde òní, wọ́n dúró fún àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn àjọ tí ọba àríwá lépa títí ṣùgbọ́n tí kò rí mú wá sábẹ́ àkóso rẹ̀.

ÍJÍBÍTÌ KÒ SÁLÀ

18, 19. Ní àwọn ọ̀nà wo ni agbára ẹni tí ń bá ọba gúúsù figẹ̀ wọngẹ̀ ti nípa lórí rẹ̀?

18 Áńgẹ́lì Jèhófà ń bá a lọ pé: “[Ọba àríwá] yóò . . . máa na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí àwọn ilẹ̀ náà; àti ní ti ilẹ̀ Íjíbítì, kì yóò jẹ́ olùsálà. Òun yóò sì ṣàkóso ní ti gidi lórí àwọn ìṣúra fífarasin ti wúrà àti fàdákà àti lórí gbogbo ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra ti Íjíbítì. Àwọn ará Líbíà àti àwọn ará Etiópíà yóò sì wà ní ìṣísẹ̀ rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 11:42, 43) Kódà, ọba gúúsù, “Íjíbítì,” kò ṣàìfara gbá àbájáde àwọn ìlànà mímú ààlà gbòòrò sí i tí ọba àríwá ń tẹ̀ lé. Bí àpẹẹrẹ, a ṣẹ́gun ọba gúúsù lọ́nà tí ó gadabú ní ilẹ̀ Vietnam. “Àwọn ará Líbíà àti àwọn ará Etiópíà” wá ńkọ́? Lọ́nà yíyẹ, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ aládùúgbò ilẹ̀ Íjíbítì ìgbàanì wọ̀nyí lè jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣáájú fún àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ alámùúlégbè “Íjíbítì” (ọba gúúsù) òde-òní, tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ibi tí ilẹ̀ wọn wà. Ní àwọn ìgbà mìíràn, wọ́n ti jẹ́ ọmọlẹ́yìn—‘wọ́n wà ní ìṣísẹ̀’—ọba àríwá.

19 Ọba àríwá ha ti ṣàkóso ‘lórí àwọn ìṣúra fífarasin ti Íjíbítì’ bí? Ní ti gidi, ó ti ní ipa alágbára lórí bí ọba gúúsù ṣe ń lo àwọn ìṣúra ọrọ̀ ajé rẹ̀. Ọba gúúsù ti tìtorí ìbẹ̀rù ẹni tí ń bá a figẹ̀ wọngẹ̀ yìí ya owó tabua sọ́tọ̀ fún àbójútó ògìdìgbó agbo ọmọ ogun orí ilẹ̀, ti ojú omi, àti ti ojú òfuurufú. Títí dé ibi tí a dé yìí, ọba àríwá ti “ṣàkóso” tàbí pé ó darí bí a ṣe ń lo ìṣúra ọba gúúsù.

ÌGBÓGUN ÌKẸYÌN

20. Báwo ni áńgẹ́lì náà ṣe ṣàpèjúwe ìgbéjàkò ìkẹyìn tí ọba àríwá yóò ṣe?

20 Ìfigẹ̀wọngẹ̀ láàárín ọba àríwá àti ọba gúúsù—bóyá ní ti ológun, ọrọ̀ ajé, tàbí lọ́nà mìíràn—ń sún mọ́ òpin rẹ̀. Ní fífi kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìfigagbága wọn ọjọ́ iwájú hàn kedere, áńgẹ́lì Jèhófà sọ pé: “Ìròyìn kan yóò wà tí yóò yọ ọ́ [ọba àríwá] lẹ́nu, láti yíyọ oòrùn àti láti àríwá, dájúdájú yóò jáde lọ nínú ìhónú ńláǹlà láti pani rẹ́ ráúráú àti láti ya ọ̀pọ̀ sọ́tọ̀ fún ìparun. Yóò sì pa àgọ́ rẹ̀ tí ó dà bí ààfin sáàárín òkun títóbi lọ́lá náà àti òkè ńlá mímọ́ Ìṣelóge; ó sì dájú pé yóò wá ní tààrà sí òpin rẹ̀, kì yóò sì sí olùrànlọ́wọ́ kankan fún un.”—Dáníẹ́lì 11:44, 45.

21. Kí ni a ṣì máa mọ̀ sí i nípa ọba àríwá?

21 Bí ilẹ̀ Soviet Union ṣe pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ ní December 1991, ìfàsẹ́yìn ńláǹlà bá ọba àríwá. Ta wá ni yóò jẹ́ ọba yìí nígbà tí Dáníẹ́lì 11:44, 45 yóò ní ìmúṣẹ? Ṣé ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tó fìgbà kan rí jẹ́ ara ilẹ̀ Soviet Union tẹ́lẹ̀ ni yóò tí yọjú ni? Tàbí, ṣe ẹni tí a mọ̀ sí ọba àríwá yóò yí padà bírí bí ó ti ṣe lọ́pọ̀ ìgbà tẹ́lẹ̀ rí ni bí? Ṣé mímú tí àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ sí i ń mú ohun ìjà àtọ́míìkì jáde yóò ṣokùnfa ìdíje ohun ìjà tuntun ni, kí ó sì nípa lórí bí a ó ṣe dá ọba yẹn mọ̀? Ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ bí àkókò ṣe ń lọ ni yóò pèsè ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Ó jẹ́ ìwà ọlọ́gbọ́n pé kí a má ṣe méfò nípa wọn. Nígbà tí ọba àríwá bá bẹ̀rẹ̀ ìgbógun rẹ̀ ìkẹyìn, gbogbo àwọn tí wọ́n bá ní ìjìnlẹ̀ òye tí a gbé karí Bíbélì yóò fòye mọ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí lọ́nà tí ó ṣe kedere.—Wo “Àwọn Ọba inú Dáníẹ́lì Orí 11,” lójú ewé 284.

22. Àwọn ìbéèrè wo ló yọjú nípa bí ọba àríwá yóò ṣe gbógun níkẹyìn?

22 Àmọ́ ṣá, a mọ ìgbésẹ̀ tí ọba àríwá máa gbé láìpẹ́. Nígbà tí ìròyìn “láti yíyọ oòrùn àti láti àríwá” bá gún un ní kẹ́ṣẹ́, yóò bẹ̀rẹ̀ ìgbógun kan ‘láti pa ọ̀pọ̀ rẹ́ ráúráú.’ Ta ni yóò dojú ogun yìí kọ? “Ìròyìn” wo sì ni yóò tanná ran irú ìjà bẹ́ẹ̀?

ÀWỌN ÌRÒYÌN ADANILÁÀMÚ TA Á KÁN

23. (a) Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì wo ni yóò ṣẹlẹ̀ kí Amágẹ́dọ́nì tó dé? (b) Àwọn wo ni “àwọn ọba láti ibi yíyọ oòrùn”?

23 Gbé ohun tí ìwé Ìṣípayá ní í sọ nípa òpin Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ẹ̀sìn èké àgbáyé, yẹ̀ wò. Kí Amágẹ́dọ́nì, “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” tó wáyé, a ó “fi iná sun” ọ̀tá paraku fún ìsìn tòótọ́ yìí “pátápátá.” (Ìṣípayá 16:14, 16; 18:2-8) Dídà tí a da àwokòtò kẹfà ti ìbínú Ọlọ́run jáde sórí odò Yúfírétì ìṣàpẹẹrẹ ni a fi ṣe àpẹẹrẹ ìṣáájú fún ìparun rẹ̀. A mú kí odò náà gbẹ ráúráú “kí a lè palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún àwọn ọba láti ibi yíyọ oòrùn.” (Ìṣípayá 16:12) Ta ni àwọn ọba wọ̀nyí? Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi kúkú ni!—Fi wé Aísáyà 41:2; 46:10, 11.

24. Ìgbésẹ̀ tí Jèhófà gbé wo ni ó lè kó ìdààmú bá ọba àríwá?

24 A ṣàpèjúwe ìparun Bábílónì Ńlá lọ́nà tí ó hàn kedere nínú ìwé Ìṣípayá, tí ó sọ pé: “Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí [àwọn ọba tí ń ṣàkóso ní àkókò òpin], àti ẹranko ẹhànnà náà [Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè], àwọn wọ̀nyí yóò kórìíra aṣẹ́wó náà, wọn yóò sì sọ ọ́ di ìparundahoro àti ìhòòhò, wọn yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán, wọn yóò sì fi iná sun ún pátápátá.” (Ìṣípayá 17:16) Èé ṣe tí àwọn alákòóso wọ̀nyí yóò fi pa Bábílónì Ńlá run? Nítorí pé “Ọlọ́run fi í sínú ọkàn-àyà wọn láti mú ìrònú òun ṣẹ.” (Ìṣípayá 17:17) Ọba àríwá wà lára àwọn alákòóso wọ̀nyí. Ó ṣeé ṣe gan-an pé kí ohun tí ó gbọ́ “láti yíyọ oòrùn” yẹn tọ́ka sí ìgbésẹ̀ tí Jèhófà gbé yìí, nígbà tí ó fi í sínú ọkàn-àyà àwọn ènìyàn tí ń ṣàkóso pé kí wọ́n pa aṣẹ́wó ẹ̀sìn paraku yìí run.

25. (a) Kí ni ọba àríwá fẹ́ dojú kọ ní pàtàkì? (b) Ibo ni ọba àríwá “pa àgọ́ rẹ̀ tí ó dà bí ààfin” sí?

25 Àmọ́, ohun kan wà ní pàtàkì tí ọba àríwá fẹ́ da ìhónú rẹ̀ lé lórí. Áńgẹ́lì náà sọ pè yóò “pa àgọ́ rẹ̀ tí ó dà bí ààfin sáàárín òkun títóbi lọ́lá náà àti òkè ńlá mímọ́ Ìṣelóge.” Nígbà ayé Dáníẹ́lì, òkun Mẹditaréníà ni òkun títóbi náà, òkè Síónì, níbi tí tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ti wà rí sì ni òkè ńlá mímọ́ náà. Nítorí náà, ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà, ńṣe ni ọba àríwá tí inú rẹ̀ ń ru fùfù lọ kógun bá àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Ní òye tẹ̀mí, ibi tí a pè ní àárín “òkun títóbi lọ́lá náà àti òkè ńlá mímọ́” dúró fún ipò tẹ̀mí tí àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Jèhófà wà. Wọ́n ti jáde kúrò nínú “òkun” aráyé tí a sọ dàjèjì sí Ọlọ́run, wọ́n sì retí láti bá Jésù Kristi ṣàkóso ní Òkè Síónì ti ọ̀run.—Aísáyà 57:20; Hébérù 12:22; Ìṣípayá 14:1.

26. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣe fi hàn, kí ní lè jẹ́ orísun ìròyìn “láti àríwá” náà?

26 Bákan náà, Ìsíkíẹ́lì, tí òun àti Dáníẹ́lì gbé ayé nígbà kan náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí a ó ṣe kọlu àwọn ènìyàn Ọlọ́run “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́.” Ó sọ pé Gọ́ọ̀gù ilẹ̀ Mágọ́gù ni yóò bẹ̀rẹ̀ ìkóguntini náà, ìyẹn ni, láti ọwọ́ Sátánì Èṣù. (Ìsíkíẹ́lì 38:14, 16) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ìhà wo ni Gọ́ọ̀gù ti wá? Jèhófà sọ nípasẹ̀ Ìsíkíẹ́lì pé: “Láti apá jíjìnnàréré jù lọ ní àríwá.” (Ìsíkíẹ́lì 38:15) Bí ó ti wù kí ìkọlù yìí le koko tó, kì yóò pa àwọn ènìyàn Jèhófà run. Ìhùmọ̀ ogun tí Jèhófà lò kí ó bàa lè pa agbo ọmọ ogun Gọ́ọ̀gù rẹ́ ráúráú ni yóò jẹ́ kí ìkọlù pàtàkì yìí wáyé. Nípa báyìí, Jèhófà sọ fún Sátánì pé: “Dájúdájú, èmi yóò . . . fi àwọn ìwọ̀ kọ́ ọ ní páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́, èmi yóò sì mú ọ jáde wá.” “Èmi yóò . . . mú kí o wá láti apá jíjìnnàréré jù lọ ní àríwá, èmi yóò sì mú ọ wá sórí àwọn òkè ńlá Ísírẹ́lì.” (Ìsíkíẹ́lì 38:4; 39:2) Nítorí náà, ìròyìn “láti yíyọ oòrùn” tí ó fa ẹ̀hónú ọba àríwá ní láti wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Ṣùgbọ́n ní ti ohun náà gan-an tí yóò wà nínú ìròyìn “láti yíyọ oòrùn àti láti àríwá” náà níkẹyìn, Ọlọ́run nìkan ni yóò pinnu rẹ̀, yóò sì di mímọ̀ nígbà tí ó bá yá.

27. (a) Èé ṣe tí Gọ́ọ̀gù yóò fi ru àwọn orílẹ̀-èdè, títí kan ọba àríwá, sókè láti kọlu àwọn ènìyàn Jèhófà? (b) Kí ni yóò jẹ́ àbáyọrí ìkọlù Gọ́ọ̀gù?

27 Ní ti Gọ́ọ̀gù, ìdí tí ó fi fi gbogbo agbára rẹ̀ gbógun yìí ni aásìkí tí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ní, àwọn tó jẹ́ pé, pa pọ̀ pẹ̀lú “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn,” wọn kì í tún ṣe apá kan ayé rẹ̀ mọ́. (Gálátíà 6:16; Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16; 17:15, 16; 1 Jòhánù 5:19) Fẹ̀tòfẹ̀tò ni Gọ́ọ̀gù ń fi kọ̀rọ̀ ojú wo “àwọn ènìyàn kan tí a kó jọpọ̀ láti inú àwọn orílẹ̀-èdè, èyí tí ń kó ọlà àti dúkìá [tẹ̀mí] jọ rẹpẹtẹ.” (Ìsíkíẹ́lì 38:12) Bí Gọ́ọ̀gù ṣe ka ipò tẹ̀mí tí àwọn Kristẹni wà sí “ìgbèríko gbalasa,” tí òun lè tẹ̀ rẹ́, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìsapá tí ó ga jù lọ láti lè mú ìparun ráúráú dé bá ohun tí ó jẹ́ ìdènà fún fífẹ́ tí ó fẹ́ máa ṣàkóso gbogbo ayé. Ṣùgbọ́n ó kùnà. (Ìsíkíẹ́lì 38:11, 18; 39:4) Nígbà tí àwọn ọba ayé, títí kan ọba àríwá, bá kọlu àwọn ènìyàn Jèhófà, wọn yóò ‘wá ní tààrà sí òpin wọn.’

‘ỌBA NÁÀ YÓÒ WÁ SÍ ÒPIN RẸ̀’

28. Kí ni a mọ̀ nípa ọjọ́ ìwájú ọba àríwá àti ọba gúúsù?

28 Ọba gúúsù kọ́ ni ọba àríwá dojú ìkọlù rẹ̀ ìkẹyìn kọ. Nítorí náà, kì í ṣe ẹni tí ń bá ọba àríwá figẹ̀ wọngẹ̀ ló pa á run. Bákan náà, ọba àríwá kò pa ọba gúúsù run. Ìjọba Ọlọ́run, “láìsí ọwọ́ [ènìyàn níbẹ̀],” ló pa ọba gúúsù run. * (Dáníẹ́lì 8:25) Ní tòótọ́, nínú ogun Amágẹ́dọ́nì, gbogbo àwọn ọba ayé ni Ìjọba Ọlọ́run yóò pa run, ó sì dájú pé èyí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọba àríwá. (Dáníẹ́lì 2:44) Dáníẹ́lì 11:44, 45 ṣàpèjúwe àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ kí ogun ìkẹyìn yẹn tó wáyé. Abájọ tí kì yóò fi “sí olùrànlọ́wọ́ kankan” nígbà tí òpin bá dé bá ọba àríwá!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 28 Wo Orí Kẹwàá ìwé yìí.

Kí Lo Lóye?

• Báwo ni ẹni tí a mọ̀ sí ọba àríwá ṣe yí padà lẹ́yìn ogun àgbáyé kejì?

• Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ọba àríwá àti ọba gúúsù níkẹyìn?

• Báwo ni o ti ṣe jàǹfààní láti inú kíkíyèsí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa ìfigẹ̀wọngẹ̀ láàárín ọba méjèèjì?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 284]

ÀWỌN ỌBA INÚ DÁNÍẸ́LÌ ORÍ KỌKÀNLÁ

Ọba Àríwá Ọba Gúúsù

Dáníẹ́lì 11:5 Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní Níkétọ̀ Pẹ́tólẹ́mì Kìíní

Dáníẹ́lì 11:6 Áńtíókọ́sì Kejì Pẹ́tólẹ́mì Kejì

(aya rẹ̀ ni Laodísì) (ọmọbìnrin rẹ̀ ni

Béréníkè)

Dáníẹ́lì 11:7-9 Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kejì Pẹ́tólẹ́mì Kẹta

Dáníẹ́lì 11:10-12 Áńtíókọ́sì Kẹta Pẹ́tólẹ́mì Kẹrin

Dáníẹ́lì 11:13-19 Áńtíókọ́sì Kẹta Pẹ́tólẹ́mì Karùn-ún

(ọmọbìnrin rẹ̀ ni Arọ́pò rẹ̀:

Kilẹopátírà Kìíní Pẹ́tólẹ́mì Kẹfà)

Àwọn arọ́pò:

Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kẹrin àti

Áńtíókọ́sì Kẹrin

Dáníẹ́lì 11:20 Ọ̀gọ́sítọ́sì

Dáníẹ́lì 11:21-24 Tìbéríù

Dáníẹ́lì 11:25, 26 Ọrélíà Ọbabìnrin Senobíà

Ilẹ̀ Ọba Róòmù

fọ́ sí wẹ́wẹ́

Dáníẹ́lì 11:27-30a Ilẹ̀ Ọba Jámánì Gẹ̀ẹ́sì, lẹ́yìn náà

(Ogun Àgbáyé Kìíní) Agbára Ayé

Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà

Dáníẹ́lì 11:30b, 31 Ìjọba Kẹta ti Hitler Agbára Ayé

(Ogun Àgbáyé Kejì) Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà

Dáníẹ́lì 11:32-43 Àwùjọ Orílẹ̀-Èdè Oníjọba Agbára Ayé

Kọ́múníìsì (Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀) Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà

Dáníẹ́lì 11:44, 45 Kò tíì dójú ọpọ́n * Agbára Ayé

Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 83 Àsọtẹ́lẹ̀ inú Dáníẹ́lì orí Kọkànlá kò sàsọtẹ́lẹ̀ orúkọ àwọn alákòóso ìṣèlú tí yóò bọ́ sípò ọba àríwá àti ti ọba gúúsù ní ìgbà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀yìn ìgbà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ nìkan ni a tó máa ń dá wọn mọ̀. Ní àfikún sí i, níwọ̀n bí gídígbò wọn ti wáyé lọ́wọ̀ọ̀wọ́, àwọn ìgbà kan wà tí kò sí gídígbò rárá—tí ọba kan a máa ṣe bó ṣe wù ú, ìkejì a sì wà bí aláìsí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 271]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 279]

‘Títa kàn-ǹ-gbọ̀n’ ọba gúúsù tún kan lílo ọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ gíga láti máa fi fimú fínlẹ̀ àti híhalẹ̀ láti gbógun jani