Ọba Méjì wọ Gídígbò
Orí Kẹtàlá
Ọba Méjì wọ Gídígbò
1, 2. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a nífẹ̀ẹ́ sí àsọtẹ́lẹ̀ tí a kọ sínú Dáníẹ́lì orí kọkànlá?
ỌBA méjì tí ń figẹ̀ wọngẹ̀ wà á kò nínú ìjà àjàmọ̀gá. Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, bí ọ̀kan bá kọ́kọ́ mókè, ìkejì á tún borí rẹ̀. Ní àwọn ìgbà mìíràn, ọba kan nínú wọn a jayé bó ṣe wù ú, tí ìkejì a sì wà bí aláìsí, àwọn sáà kan sì wà tí kò ní sí gídígbò. Àmọ́, ńṣe ni ogun á tún ṣàdédé rú yọ, wọn a sì tún wọ gídígbò. Lára àwọn tí wọ́n ti kópa nínú rìgbòrìyẹ̀ yìí ni Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní Níkétọ̀ ọba Síríà, Pẹ́tólẹ́mì Lágọ́sì ọba Íjíbítì, Kilẹopátírà Kìíní ọmọbìnrin ọba Síríà tí ó di Ọbabínrin ní Íjíbítì, Ọ̀gọ́sítọ́sì àti Tìbéríù tí wọ́n jẹ́ Olú Ọba Róòmù, àti Senobíà Ọbabìnrin ìlú Pálímírà. Bí gídígbò náà ṣe ń sún mọ́ òpin rẹ̀, ilẹ̀ Germany ti Násì, àpapọ̀ orílẹ̀-èdè elétò ìjọba Kọ́múníìsì, Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti kópa níbẹ̀ pẹ̀lú. Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn agbára ìṣèlú wọ̀nyí tí ó mọ ibi tí ọ̀ràn náà yóò forí tì sí. Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] ọdún sẹ́yìn ni áńgẹ́lì Jèhófà ti kéde àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá yìí fún wòlíì Dáníẹ́lì.—Dáníẹ́lì, orí kọkànlá.
2 Yóò ti dùn mọ́ Dáníẹ́lì tó láti gbọ́ bí áńgẹ́lì náà ṣe ń ṣí ọ̀ràn ìfigagbága láàárín ọba méjì tí yóò jẹ lọ́jọ́ iwájú payá fún un lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́! Àwa náà fẹ́ mọ̀ nípa rìgbòrìyẹ̀ náà, nítorí pé àwọn ọba méjèèjì ṣì wà lẹ́nu ìjàkadì títí di ìgbà tiwa yìí. Bí a bá rí bí ìtàn ṣe fi hàn pé apá àkọ́kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, yóò túbọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àti ìdánilójú tí a ní lágbára sí i pé apá tí ó kẹ́yìn nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí a kọ sílẹ̀ náà yóò ṣẹlẹ̀ dájúdájú. Bí a bá kíyè sí àsọtẹ́lẹ̀ yìí, a óò lè mọ ibi tí a wà gan-an níbi tí ìtàn ayé dé yìí. Yóò sì tún jẹ́ kí ìpinnu wa láti wà láìdásí-tọ̀tún-tòsì nínú gídígbò náà túbọ̀ lágbára sí i bí a Sáàmù 146:3, 5) Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a tẹ́tí sílẹ̀ tọkàntara bí áńgẹ́lì Jèhófà ṣe ń bá Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀.
ṣe ń fara balẹ̀ dúró de ìgbà tí Ọlọ́run yóò gbé ìgbésẹ̀ nítorí tiwa. (Ó GBÓGUN DÌDE SÍ ÌJỌBA GÍRÍÌSÌ
3. Ta ni áńgẹ́lì ṣètìlẹyìn fún “ní ọdún kìíní Dáríúsì ará Mídíà”?
3 Áńgẹ́lì náà sọ pé: “Ní tèmi, ní ọdún kìíní Dáríúsì ará Mídíà [ọdún 539 tàbí 538 ṣááju Sànmánì Tiwa], mo dúró bí afúnnilókun àti bí odi agbára fún un.” (Dáníẹ́lì 11:1) Kò sí Dáríúsì láyé mọ́ nígbà yẹn, síbẹ̀ áńgẹ́lì náà sọ pé ìgbà ìṣàkóso rẹ̀ ni ìhìn iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀. Ọba yẹn ni ó pàṣẹ pé kí wọ́n yọ Dáníẹ́lì kúrò nínú ihò kìnnìún. Dáríúsì sì tún pàṣẹ pé kí gbogbo ọmọ abẹ́ ìjọba òun bẹ̀rù Ọlọ́run Dáníẹ́lì. (Dáníẹ́lì 6:21-27) Àmọ́, kì í ṣe Dáríúsì ará Mídíà ni ẹni tí áńgẹ́lì náà dúró tì gbágbáágbá bí kò ṣe alábàákẹ́gbẹ́ áńgẹ́lì náà, Máíkẹ́lì—ọmọ aládé àwọn ènìyàn Dáníẹ́lì. (Fi wé Dáníẹ́lì 10:12-14.) Áńgẹ́lì Ọlọ́run ṣe ìtìlẹyìn yìí nígbà tí Máíkẹ́lì ń bá ẹ̀mí èṣù ọmọ aládé ilẹ̀ Mídíà òun Páṣíà fà á.
4, 5. Àwọn wo ni ọba Páṣíà mẹ́rin tí a sọ tẹ́lẹ̀ náà?
4 Áńgẹ́lì Ọlọ́run ń bá a lọ pé: “Wò ó! Ọba mẹ́ta ni yóò ṣì dìde fún Páṣíà, ẹ̀kẹrin yóò sì kó ọrọ̀ jọ tìrìgàngàn ju gbogbo àwọn yòókù. Gbàrà tí ó bá sì ti di alágbára nínú ọrọ̀ rẹ̀, yóò gbé ohun gbogbo dìde lòdì sí ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì.” (Dáníẹ́lì 11:2) Àwọn wo ni àwọn ọba ilẹ̀ Páṣíà yìí?
5 Ọba mẹ́ta àkọ́kọ́ ni Kírúsì Ńlá, Kanbáísísì Kejì, àti Dáríúsì Kìíní (Hisitápísì). Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé oṣù méje péré ni Bádíyà (tàbí ẹnì kan tí ó fèrú jọba tí ń jẹ́ Gáúmátà) fi jọba, àsọtẹ́lẹ̀ náà kò ṣírò ìṣàkóso tirẹ̀ tí ó jẹ́ ìgbà kúkúrú mọ́ ọn. Ní ọdún 490 ṣááju Sànmánì Tiwa, Dáríúsì Kìíní, ọba kẹta, gbìyànjú láti gbógun ja ilẹ̀ Gíríìsì lẹ́ẹ̀kejì. Àmọ́, wọ́n borí àwọn ará Páṣíà ní ìlú Márátọ̀n, wọ́n bá sá padà sí Éṣíà Kékeré. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáríúsì fẹ̀sọ̀ múra sílẹ̀ láti gbé ogun ja Gíríìsì síwájú sí i, kò lè ṣe é kí ó tó kú ní ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà. Ọba “kẹrin,” ọmọ rẹ̀ Sásítà Kìíní, tí ó rọ́pò rẹ̀ ni ó ṣe é. Òun Ẹ́sítérì 1:1; 2:15-17.
ni Ahasuwérúsì Ọba tí ó fi Ẹ́sítérì ṣaya.—6, 7. (a) Báwo ni ọba kẹrin ṣe “gbé ohun gbogbo dìde lòdì sí ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì”? (b) Kí ni àbáyọrí ogun tí Sásítà gbé ja ilẹ̀ Gíríìsì?
6 Lóòótọ́, Sásítà Kìíní “gbé ohun gbogbo dìde lòdì sí ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì,” èyíinì ni àpapọ̀ àwọn ìpínlẹ̀ tí ń fúnra wọn ṣèjọba ní ilẹ̀ Gíríìsì. Ìwé The Medes and Persians—Conquerors and Diplomats sọ pé: “Bí àwọn ẹmẹ̀wà ààfin arógunyọ̀ ṣe ń ti Sásítà, ló bá ń gbógun ṣáá, lórí ilẹ̀ àti lójú òkun.” Herodotus, òpìtàn ilẹ̀ Gíríìsì ti ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa, kọ̀wé pé “kò sí ètò ogun jíjà kankan tí ó tó eléyìí rárá.” Àkọsílẹ̀ tó kọ sọ pé agbo ọmọ ogun ojú òkun rẹ̀ “jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ó lé egbèjì-dín-láàádọ́rùn-ún lé mẹ́wàá [517,610] ènìyàn lápapọ̀. Iye àwọn sójà tí ń fẹsẹ̀ rìn jẹ́, ọ̀kẹ́ márùn-dín-láàádọ́rùn-ún [1,700,000]; àwọn agẹsinjagun jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́rin [80,000]; kí a tún fi àwọn Árábù tí ń gun ràkúnmí àti àwọn ará Líbíà tí ń lo kẹ̀kẹ́ ẹṣin, tí mo lè sọ pé wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ kan [20,000] kún un. Nítorí náà, agbo ọmọ ogun orí ilẹ̀ àti ojú okùn náà lápapọ̀ yóò jẹ́ ọ̀kẹ́ márùndínlọ́gọ́fà ó lé egbèjì-dín-láàádọ́rùn-ún lé mẹ́wàá [2,317,610] ènìyàn.”
7 Sásítà Kìíní kò pète ohun mìíràn yàtọ̀ sí pé kí ó ṣẹ́gun wọn pátápátá, nítorí náà, ó dojú agbo ọmọ ogun rẹ̀ tìrìgàngàn kọ ilẹ̀ Gíríìsì lọ́dún 480 ṣááju Sànmánì Tiwa. Bí àwọn ará Páṣíà ṣe já ọgbọ́n ìdánidúró tí àwọn ará Gíríìsì ń lò fún wọn ní Tamopílè, wọ́n bá run Áténì. Àmọ́, a ṣẹ́gun wọn lọ́nà tí ó gadabú ní Sálámísì. Ilẹ̀ Gíríìsì tún ṣẹ́gun wọn ní Pílátéà lọ́dún 479 ṣááju Sànmánì Tiwa. Nínú ọdún mẹ́tàlélógóje tí ó tẹ̀ lé e, kò sí ìkankan lára àwọn ọba méje tí ó gorí ìtẹ́ tẹ̀ lé Sásítà ní Ilẹ̀ Ọba Páṣíà, tí ó ṣígun lọ bá ilẹ̀ Gíríìsì. Àmọ́, ọba ńlá kan wá jẹ lórí ilẹ̀ Gíríìsì.
A PÍN ÌJỌBA ŃLÁ KAN SÍ MẸ́RIN
8. “Ọba alágbára ńlá” wo ni ó dìde, báwo ni ó sì ṣe “ṣàkóso pẹ̀lú àṣẹ ìṣàkóso tí ó gbilẹ̀”?
8 Áńgẹ́lì náà sọ pé: “Dájúdájú, ọba alágbára ńlá kan yóò Dáníẹ́lì 11:3) Alẹkisáńdà, tí ó jẹ́ ẹni ogún ọdún “dìde” gẹ́gẹ́ bí ọba Makedóníà ní ọdún 336 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ní tòótọ́, ó di “ọba alágbára ńlá kan”—Alẹkisáńdà Ńlá. Bí ó ṣe fẹ́ ṣe ohun tí baba rẹ̀ Fílípì Kejì wéwèé kalẹ̀, ó gba àwọn ìpínlẹ̀ Páṣíà tí ó wà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn. Bí àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin [47,000] ṣe sọdá odò Yúfírétì àti ti Tígírísì, ńṣe ni wọ́n fọ́n àwọn ọmọ ogun Dáríúsì Kẹta tí wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méjìlá ààbọ̀ [250,000] ká ní Gaugamela. Dáríúsì bá fẹsẹ̀ fẹ, a sì ṣìkà pa á, bí ìlà ọba tí ń jẹ ní ilẹ̀ Páṣíà ṣe dópin nìyẹn. Ilẹ̀ Gíríìsì wá di agbára ayé wàyí, Alẹkisáńdà sì ‘ṣàkóso pẹ̀lú àṣẹ ìṣàkóso tí ó gbilẹ̀, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.’
dìde, yóò sì ṣàkóso pẹ̀lú àṣẹ ìṣàkóso tí ó gbilẹ̀, yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.” (9, 10. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn pé ìjọba Alẹkisáńdà kò ní jẹ́ ti ìran àtẹ̀lé rẹ̀ ṣe já sí òótọ́?
9 Alẹkisáńdà kò ṣàkóso pẹ́ lórí ayé, nítorí áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ síwájú sí i pé: “Nígbà tí ó bá sì ti dìde, a óò fọ́ ìjọba rẹ̀, a ó sì pín in sí ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ojú ọ̀run, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún ìran àtẹ̀lé rẹ̀, kì í sì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ìṣàkóso rẹ̀, èyí tí ó fi ṣàkóso; nítorí pé a ó fa ìjọba rẹ̀ tu tigbòǹgbò-tigbòǹgbò, àní fún àwọn mìíràn dípò ìwọ̀nyí.” (Dáníẹ́lì 11:4) Alẹkisáńdà kò tíì pé ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n nígbà tí àìsàn òjijì gbẹ̀mí rẹ̀ ní Bábílónì lọ́dún 323 ṣááju Sànmánì Tiwa.
10 Ilẹ̀ ọba gbígbòòrò tí Alẹkisáńdà ní kò bọ́ sọ́wọ́ “ìran àtẹ̀lé rẹ̀.” Kò tó ọdún méje tí Fílípì Kẹta Árídíọ́sì, arákùnrin rẹ̀, fi ṣàkóso tí Ólíńpíásì, ìyá Alẹkisáńdà fi sọ pé kí wọ́n pa á lọ́dún 317 ṣááju Sànmánì Tiwa. Alẹkisáńdà Kẹrin, ọmọ Alẹkisáńdà, ṣàkóso títí di ọdún 311 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Kasáńdà, ọ̀kan lára ọ̀gágun baba rẹ̀, bá ṣekú pa á. Hérákù, ọmọ àlè tí Alẹkisáńdà bí, wọ́nà láti fi orúkọ baba rẹ̀ jọba, ṣùgbọ́n, a ṣìkà pa á lọ́dún 309 ṣááju Sànmánì Tiwa. Bí ìlà Alẹkisáńdà ṣe dópin nìyẹn, tí “àṣẹ ìṣàkóso” sì lọ kúrò nínú ìdílé rẹ̀.
11. Báwo ni a ṣe “pín” ìjọba Alẹkisáńdà “sí ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ojú ọ̀run”?
11 Lẹ́yìn ikú Alẹkisáńdà, a ‘pín ìjọba rẹ̀ sí ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.’ Àwọn ọ̀gágun rẹpẹtẹ tí ó ní bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jà bí wọ́n ṣe ń bá ara wọn du ìpínlẹ̀. Ọ̀gágun Antigónù Kìíní, tí ó jẹ́ olójú kan, gbìyànjú láti kó gbogbo ilẹ̀ ọba Alẹkisáńdà sábẹ́. Ṣùgbọ́n, ojú ogun Ipisọ́sì ní Fíríjíà ni a ti pa á. Nígbà tí ó fi máa di ọdún 301 ṣááju Sànmánì Tiwa, mẹ́rin lára àwọn ọ̀gágun Alẹkisáńdà ti gba agbára lórí ìpínlẹ̀ gbígbòòrò tí ọ̀gá wọn ṣẹ́gun. Kasáńdà ṣàkóso Makedóníà àti Gíríìsì. Lisimákù gba àkóso lórí Éṣíà Kékeré àti Tírésì. Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní Níkétọ̀ kó Mesopotámíà òun Síríà sábẹ́. Pẹ́tólẹ́mì Lágọ́sì sì gba Íjíbítì àti Palẹ́sìnì. Ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ gan-an ló ṣẹlẹ̀, a pín ilẹ̀ ọba ńláǹlà ti Alẹkisáńdà sí ìjọba Hélénì mẹ́rin.
ỌBA MÉJÌ TÍ Ń FIGẸ̀ WỌNGẸ̀ YỌJÚ
12, 13. (a) Báwo ni a ṣe dín ìjọba mẹ́rin tí ó jẹ́ ti Hélénì kù sí méjì? (b) Ìlà ọba wo ni Sẹ̀lẹ́úkọ́sì bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ilẹ̀ Síríà?
12 Kasáńdà kú lẹ́yìn ọdún mélòó kan tí ó gorí àlééfà, nígbà tí ó sì di ọdún 285 ṣááju Sànmánì Tiwa Lisimákù gba apá ilẹ̀ Yúróòpù nínú Ilẹ̀ Ọba Gíríìkì. Ní ọdún 281 ṣááju Sànmánì Tiwa, Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní Níkétọ̀ pa Lisimákù lójú ogun, èyí ni Sẹ̀lẹ́úkọ́sì fi gba àkóso apá tí ó pọ̀ jù nínú ìpínlẹ̀ Éṣíà. Antigónù Kejì Gonatásì, ọmọ-ọmọ ọ̀kan lára àwọn ọ̀gágun Alẹkisáńdà, gorí ìtẹ́ Makedóníà ní ọdún 276 ṣááju Sànmánì Tiwa. Nígbà tí ó ṣe, Makedóníà wá gbára lé ilẹ̀ Róòmù, bí ó ṣe di ọ̀kan nínú ìpínlẹ̀ Róòmù níkẹyìn ní ọdún 146 ṣááju Sànmánì Tiwa nìyẹn.
13 Ó ti wá ku méjì sójú ọpọ́n nínú ìjọba mẹ́rin ti àwọn Hélénì—ọ̀kan tí ó wà lábẹ́ Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní Níkétọ̀ àti ìkejì tí ó wà Ìṣe 11:25, 26; 13:1-4) A ṣìkà pa Sẹ̀lẹ́úkọ́sì ní ọdún 281 ṣááju Sànmánì Tiwa, ṣùgbọ́n ìlà ọba tí ó dá sílẹ̀ ń bá ìṣàkóso lọ títí di ọdún 64 ṣááju Sànmánì Tiwa nígbà tí Ọ̀gágun Gínéọ́sì Pọ́ńpè, ara Róòmù, sọ Síríà di ara ìpínlẹ̀ Róòmù.
lábẹ́ Pẹ́tólẹ́mì Lágọ́sì. Sẹ̀lẹ́úkọ́sì ni ó bẹ̀rẹ̀ ìlà àwọn ọba tí ń jẹ́ Sẹ̀lẹ́úkọ́sì, tí ń jọba ní Síríà. Ara ìlú tí ó tẹ̀ dó ni Áńtíókù—olú ìlú tuntun fún ilẹ̀ Síríà—àti ibùdókọ̀ òkun ti Séléúkíà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ́ni ní Áńtíókù lẹ́yìn ìgbà náà, ibẹ̀ ni a ti kọ́kọ́ pe àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní Kristẹni. (14. Ìgbà wo ni a bẹ̀rẹ̀ ìlà ọba ti Pẹ́tólẹ́mì ní Íjíbítì?
14 Ìjọba tí ó wà fún ìgbà pípẹ́ jú lọ nínú ìjọba Hélénì mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ni ti Pẹ́tólẹ́mì Lágọ́sì, tàbí Pẹ́tólẹ́mì Kìíní, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba lọ́dún 305 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ìlà àwọn ọba tí ń jẹ́ Pẹ́tólẹ́mì, tí òun bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, ń bá a lọ láti ṣàkóso Íjíbítì títí tí Íjíbítì fi ṣubú sọ́wọ́ Róòmù ní ọdún 30 ṣááju Sànmánì Tiwa.
15. Ọba alágbára méjì wo ni ó jẹyọ láti inú ìjọba mẹ́rin tí ó jẹ́ ti àwọn Hélénì, ìjàkadì wo ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ rẹ̀?
15 Bí ọba alágbára méjì—Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní Níkétọ̀ tí ń ṣàkóso Dáníẹ́lì orí kọkànlá, ti bẹ̀rẹ̀. Áńgẹ́lì Jèhófà kò sọ orúkọ àwọn ọba wọ̀nyí, nítorí pé ẹni tí ọba méjèèjì jẹ́ àti orílẹ̀-èdè tí wọn ó ti wá yóò máa yí padà bí ọ̀rúndún ṣe ń gorí ọ̀rúndún. Áńgẹ́lì náà fo àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí kò ṣe pàtàkì, kìkì àwọn ọba àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì nínú gídígbò náà nìkan ni ó mẹ́nu kàn.
Síríà àti Pẹ́tólẹ́mì Kìíní tí ń ṣàkóso Íjíbítì—ṣe jẹyọ nìyẹn láti inú ìjọba mẹ́rin ti Hélénì. Ọ̀dọ̀ ọba méjèèjì yìí ni ìjàkadì láàárín “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù,” tí ó ti ń bá a bọ̀ láti ọjọ́ pípẹ́, tí a ṣàpèjúwe nínúGÍDÍGBÒ NÁÀ BẸ̀RẸ̀
16. (a) Ìhà àríwá àti gúúsù ta ni àwọn ọba méjèèjì wà? (b) Àwọn ọba wo ni ó kọ́kọ́ bọ́ sí ipò “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù”?
16 Tẹ́tí sílẹ̀! Áńgẹ́lì Jèhófà ṣàpèjúwe gídígbò tí ó gba àfiyèsí yìí pé: “Ọba gúúsù yóò sì di alágbára, àní ọ̀kan lára àwọn ọmọ aládé rẹ̀ [ti Alẹkisáńdà]; [ọba àríwá] yóò sì borí rẹ̀, yóò sì ṣàkóso pẹ̀lú àṣẹ ìṣàkóso tí ó gbilẹ̀ ju ti agbára ìṣàkóso ẹni yẹn lọ.” (Dáníẹ́lì 11:5) “Ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” tí a fi pè wọ́n tọ́ka sí àwọn ọba tí ó wà níhà àríwá àti èyí tí ó wà níhà gúúsù ilẹ̀ àwọn ènìyàn Dáníẹ́lì, àwọn ẹni tí a ti dá sílẹ̀ kúrò ní ìgbèkùn Bábílónì nígbà yẹn, tí a sì ti mú padà bọ̀ sí ilẹ̀ Júdà. Pẹ́tólẹ́mì Kìíní ti ilẹ̀ Íjíbítì ni ó kọ́kọ́ di “ọba gúúsù.” Ọ̀kan lára àwọn ọ̀gágun Alẹkisáńdà, tí ó borí Pẹ́tólẹ́mì Kìíní tí ó sì “ṣàkóso pẹ̀lú àṣẹ ìṣàkóso tí ó gbilẹ̀” ni Ọba Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní Níkétọ̀ ti Síríà. Òun ni ó dúró ní ipò “ọba àríwá.”
17. Abẹ́ ìṣàkóso ta ni ilẹ̀ Júdà wà ní ìbẹ̀rẹ̀ gídígbò àárín ọba àríwá àti ọba gúúsù?
17 Ní ìbẹ̀rẹ̀ gídígbò náà, abẹ́ àkóso ọba gúúsù ni ilẹ̀ Júdà wà. Láti nǹkan bí ọdún 320 ṣááju Sànmánì Tiwa, Pẹ́tólẹ́mì Kìíní mú kí àwọn Júù wá máa gbé ní àdádó ní ilẹ̀ Íjíbítì.
Àdádó tí ó jẹ́ ti àwọn Júù fìdí múlẹ̀ ní Alẹkisáńdíríà, níbi tí Pẹ́tólẹ́mì Kìíní kọ́ ilé ìkówèésí kan tí ó lókìkí sí. Àwọn Júù tí ó wà ní Júdà wà lábẹ́ àṣẹ àwọn Pẹ́tólẹ́mì ti ilẹ̀ Íjíbítì, ọba gúúsù títí di ọdún 198 ṣááju Sànmánì Tiwa.18, 19. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, báwo ni ọba méjèèjì tí ń figẹ̀ wọngẹ̀ náà ṣe jùmọ̀ ṣe “ètò ìfẹ̀tọ́-bánilò-lọ́gbọọgba”?
18 Áńgẹ́lì náà sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọba méjèèjì pé: “Ní òpin àwọn ọdún mélòó kan, wọn yóò bá ara wọn ní àjọṣepọ̀, ọmọbìnrin ọba gúúsù fúnra rẹ̀ yóò sì wá sọ́dọ̀ ọba àríwá láti ṣe ètò ìfẹ̀tọ́-bánilò-lọ́gbọọgba. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin náà kì yóò ní agbára ní apá rẹ̀; ọkùnrin náà kì yóò sì dúró, bẹ́ẹ̀ sì ni apá rẹ̀; a ó sì jọ̀wọ́ ọmọbìnrin náà lọ́wọ́, òun fúnra rẹ̀, àti àwọn tí ó mú ọmọbìnrin náà wá àti ọkùnrin náà tí ó bí i, àti ẹni tí ó sọ ọmọbìnrin náà di alágbára ní àwọn àkókò wọnnì.” (Dáníẹ́lì 11:6) Báwo ni èyí ṣe ṣẹlẹ̀?
19 Àsọtẹ́lẹ̀ náà kò ka Áńtíókọ́sì Kìíní, ọmọ Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní Níkétọ̀ tí ó rọ́pò rẹ̀ sí, nítorí pé kò bá ọba gúúsù ja ogun àjàmọ̀gá. Ṣùgbọ́n Áńtíókọ́sì Kejì tí ó rọ́pò rẹ̀ bá Pẹ́tólẹ́mì Kejì, ọmọ Pẹ́tólẹ́mì Kìíní, jagun fún ìgbà pípẹ́. Áńtíókọ́sì Kejì jẹ́ ọba àríwá, tí Pẹ́tólẹ́mì Kejì sì jẹ́ ọba gúúsù. Áńtíókọ́sì Kejì fẹ́ Laodísì, wọ́n sì bí ọmọkùnrin kan tí ń jẹ́ Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kejì, nígbà tí Pẹ́tólẹ́mì Kejì bí ọmọbìnrin tí ń jẹ́ Béréníkè. Lọ́dún 250 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn ọba méjèèjì jùmọ̀ ṣe “ètò ìfẹ̀tọ́-bánilò-lọ́gbọọgba.” Ohun tí Áńtíókọ́sì Kejì san lórí àjọṣepọ̀ yìí ni pé ó kọ Laodísì aya rẹ̀ sílẹ̀, ó sì lọ fẹ́ Béréníkè, “ọmọbìnrin ọba gúúsù fúnra rẹ̀.” Ọmọkùnrin tí Béréníkè bí fún un ni ó sì wà ní ìlà láti jogún ìtẹ́ Síríà dípò àwọn ọmọkùnrin Laodísì.
20. (a) Báwo ni “apá” Béréníkè kò ṣe dúró? (b) Báwo ni a ṣe jọ̀wọ́ Béréníkè, ‘àti àwọn tí ó mú un wá’ àti ‘ẹni tí ó sọ ọ́ di alágbára’ lọ́wọ́? (d) Ta ni ó di ọba Síríà lẹ́yìn tí Áńtíókọ́sì Kejì pàdánù “apá rẹ̀,” tàbí agbára tó ní?
20 “Apá” tàbí agbára tí ó ń ti Béréníkè lẹ́yìn ni Pẹ́tólẹ́mì Kejì baba rẹ̀. Nígbà tí baba rẹ̀ kú lọ́dún 246 ṣááju Sànmánì
Tiwa, Béréníkè kò “ní agbára ní apá rẹ̀” lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀ mọ́. Áńtíókọ́sì Kejì pa á tì, ó tún padà lọ fẹ́ Laodísì, ọmọkùnrin tí wọ́n sì bí ni ó sọ pé yóò rọ́pò òun. A pa Béréníkè àti ọmọkùnrin rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú ìwéwèé Laodísì. Ẹ̀rí fi hàn pé ohun kan náà ni ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìránṣẹ́ tí ó mú Béréníkè wá sí Síríà láti Íjíbítì, ìyẹn, “àwọn tí ó mú ọmọbìnrin náà wá.” Kódà, Laodísì gbé májèlé fún Áńtíókọ́sì Kejì jẹ, fún ìdí èyí “apá rẹ̀” tàbí agbára tó ní, pẹ̀lú ‘kò sì dúró.’ Nípa bẹ́ẹ̀, ikú pa baba Béréníkè—“ọkùnrin náà tí ó bí i”—àti ọkọ rẹ̀ ará Síríà—ẹni tí ó sọ ọmọbìnrin náà di “alágbára” fún sáà kan. Èyí wá mú kí Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kejì, ọmọ Laodísì, di ọba Síríà. Kí ni Pẹ́tólẹ́mì tí yóò jọba tẹ̀ lé e yóò ṣe nípa gbogbo èyí?ỌBA KAN GBẸ̀SAN PÍPA TÍ A PA ARÁBÌNRIN RẸ̀
21. (a) Ta ni “ẹnì kan . . . láti inú èéhù gbòǹgbò” Béréníkè, báwo sì ni ó ṣe “dìde”? (b) Báwo ni Pẹ́tólẹ́mì Kẹta ṣe wá “lòdì sí odi agbára ọba àríwá” tí ó sì borí rẹ̀?
21 Áńgẹ́lì náà sọ pé: “Ẹnì kan yóò sì dìde láti inú èéhù gbòǹgbò ọmọbìnrin náà ní ipò ọkùnrin náà, yóò sì wá lòdì sí ẹgbẹ́ ológun àti lòdì sí odi agbára ọba àríwá, yóò sì gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí wọn, yóò sì borí.” (Dáníẹ́lì 11:7) Arákùnrin Béréníkè ni “ẹnì kan . . . láti inú èéhù,” tàbí “gbòǹgbò” àwọn òbí rẹ̀. Nígbà tí baba ọmọkùnrin náà kú, òun ni ó “dìde” gẹ́gẹ́ bí ọba gúúsù, ìyẹn Pẹ́tólẹ́mì Kẹta tí ó jẹ́ Fáráò ilẹ̀ Íjíbítì. Ní kíá, ó gbéra láti lọ gbẹ̀san pípa tí a pa arábìnrin rẹ̀. Bí ó ṣe gbé ogun lọ bá Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kejì, ọba Síríà, ẹni tí Laodísì lò láti pa Béréníkè àti ọmọ rẹ̀, ó wá “lòdì sí odi agbára ọba àríwá.” Pẹ́tólẹ́mì Kẹta gba ibi odi agbára ní Áńtíókù, ó sì pa Laodísì. Ó tẹ̀ síwájú síhà ìlà-oòrùn ilẹ̀ ọba àríwá, ó kó ìkógun ní ilẹ̀ ọba Babilóníà, ó sì tẹ̀ síwájú sí ilẹ̀ Íńdíà.
22. Kí ni Pẹ́tólẹ́mì Kẹta kó padà wá sí Íjíbítì, èé sì ti ṣe tí ó fi ‘dúró ní títakété sí ọba àríwá fún ọdún mélòó kan’?
22 Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ fún wa pé: “Àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́run wọn, pẹ̀lú ère dídà wọn, pẹ̀lú àwọn ohun èlò fàdákà àti ti wúrà wọn fífani-lọ́kàn-mọ́ra, àti pẹ̀lú àwọn Dáníẹ́lì 11:8) Ní èyí tí ó ju igba ọdún ṣáájú, Kanbáísísì Kejì, ọba Páṣíà ṣẹ́gun ilẹ̀ Íjíbítì, ó sì kó àwọn ọlọ́run ilẹ̀ Íjíbítì, “ère dídà wọn,” dání lọ sílé. Bí Pẹ́tólẹ́mì Kẹta ṣe kó ìkógun ní Súsà tí ó jẹ́ olú ìlú ọba ilẹ̀ Páṣíà tẹ́lẹ̀ rí, ó gba àwọn ọlọ́run wọ̀nyí padà, ó sì kó wọn ní “òǹdè” wá sí ilẹ̀ Íjíbítì. Ó tún kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ “àwọn ohun èlò fàdákà àti ti wúrà . . . fífani-lọ́kàn-mọ́ra” ní ìkógun wá sílé. Nítorí ọ̀tẹ̀ tí Pẹ́tólẹ́mì Kẹta ní láti paná rẹ̀ nílé, ó “dúró ní títakété sí ọba àríwá,” láìtún ṣe é lọ́ṣẹ́ kankan.
òǹdè ni yóò wá sí Íjíbítì. Fún ọdún mélòó kan, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró ní títakété sí ọba àríwá.” (ỌBA SÍRÍÀ GBẸ̀SAN
23. Èé ṣe tí ọba àríwá fi “padà lọ sí ilẹ̀ rẹ̀” lẹ́yìn tí ó ti wá sínú ilẹ̀ àkóso ọba gúúsù?
23 Kí ni ọba àríwá wá ṣe? A sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Ní ti tòótọ́, òun yóò wá sínú ìjọba ọba gúúsù, yóò sì padà lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 11:9) Ọba àríwá—Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kejì, ọba Síríà—gbẹ̀san. Ó wá sínú “ìjọba” tàbí ìpínlẹ̀ ọba gúúsù ti Íjíbítì, ṣùgbọ́n a ṣẹ́gun rẹ̀. Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kejì bá kó ìwọ̀nba ọmọ ogun rẹ̀ tí ó kù, ó sì “padà lọ sí ilẹ̀ rẹ̀,” ní nǹkan bí ọdún 242 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó padà sí Áńtíókù olú ìlú ilẹ̀ Síríà. Nígbà tí ó kú, ọmọ rẹ̀ Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kẹta rọ́pò rẹ̀.
24. (a) Kí ní ṣẹlẹ̀ sí Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kẹta? (b) Báwo ni Áńtíókọ́sì Kẹta ọba Síríà ṣe ‘dé, tí ó kún, tí ó sì kọjá’ ní ilẹ̀ ọba gúúsù?
24 Kí ni a sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọmọ Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kejì ọba Síríà? Áńgẹ́lì náà sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Wàyí o, ní ti àwọn ọmọ rẹ̀, wọn yóò ru ara wọn sókè, wọn yóò sì kó ogunlọ́gọ̀ ẹgbẹ́ ológun ńlá jọpọ̀ ní ti gidi. Ní dídé, dájúdájú yóò dé, yóò kún, yóò sì kọjá. Ṣùgbọ́n yóò padà, yóò sì ru ara rẹ̀ sókè dé iyàn-níyàn odi agbára rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 11:10) Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kẹta kò ṣàkóso pé ọdún mẹ́ta tí a fi yọ́ kẹ́lẹ́ pa á. Áńtíókọ́sì Kẹta, arákùnrin rẹ̀, rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́ Síríà. Ọmọ Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kejì yìí kó agbo ọmọ ogun ńláǹlà jọ láti lọ gbéjà ko ọba gúúsù tí ó jẹ́ Pẹ́tólẹ́mì Kẹrin nígbà yẹn. Ọba àríwá tuntun tí Síríà ní yìí kẹ́sẹ járí nínú ìjà tí ó bá Íjíbítì jà, ó sì gba ibùdókọ̀ òkun Séléúkíà, ìgbèríko Koele ti Síríà, ìlú Tírè àti Pẹ́tólẹ́máísì, àti àwọn ìlú tí wọ́n wà ní sàkáání rẹ̀ padà. Ó borí ọmọ ogun Ọba Pẹ́tólẹ́mì Kẹrin, ó sì gba ọ̀pọ̀ ìlú Júdà. Ní ìgbà ìrúwé ọdún 217 ṣááju Sànmánì Tiwa, Áńtíókọ́sì Kẹta kúrò ní Pẹ́tólẹ́máísì, ó sì lọ síhà àríwá, “dé iyàn-níyàn odi agbára rẹ̀” ní ìlú Síríà. Àmọ́, ìyípadà máa tó bá a.
Ọ̀RÀN YÍ PADÀ BÌRÍ
25. Ibo ni Pẹ́tólẹ́mì Kẹrin ti gbógun pàdé Áńtíókọ́sì Kẹta, kí sì ni a ‘fi lé’ ọba gúúsù ti ilẹ̀ Íjíbítì “lọ́wọ́”?
25 Bíi ti Dáníẹ́lì, àwa náà ń fi ìháragàgà tẹ́tí sílẹ̀ bí áńgẹ́lì Jèhófà ṣe tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ọba gúúsù yóò sì mú ara rẹ̀ korò, yóò sì jáde lọ láti bá a jà, èyíinì ni, pẹ̀lú ọba àríwá; dájúdájú, yóò mú kí ogunlọ́gọ̀ ńlá dìde, a ó sì fi ogunlọ́gọ̀ náà lé ẹni yẹn lọ́wọ́ ní ti gidi.” (Dáníẹ́lì 11:11) Ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [75,000] ọmọ ogun ni Pẹ́tólẹ́mì Kẹrin, ọba gúúsù, kó lọ́wọ́, ó sì tẹ̀ síwájú sí ìhà àríwá láti lọ gbéjà ko ọ̀tá rẹ̀. Áńtíókọ́sì Kẹta, ọba àríwá ti Síríà kó “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí ó jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹgbàárin [68,000] jọ láti fi gbéjà kò ó. Ṣùgbọ́n a fi “ogunlọ́gọ̀ náà lé” ọba gúúsù “lọ́wọ́” nínú ogun tí wọ́n jà ní Ráfíà, ìlú etíkun kan nítòsí ààlà ilẹ̀ Íjíbítì.
26. (a) “Ogunlọ́gọ̀” wo ni ọba gúúsù kó lọ nígbà ogun ní Ráfíà, kí sì ni a sọ nínú àdéhùn àlàáfíà tí wọ́n ṣe níbẹ̀? (b) Báwo ni Pẹ́tólẹ́mì Kẹrin kò ṣe “lo ipò alágbára rẹ̀”? (d) Ta ní tún di ọba gúúsù tẹ̀ lé èyí?
26 Àsọtẹ́lẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Dájúdájú, a óò kó ogunlọ́gọ̀ náà lọ. Ọkàn-àyà rẹ̀ yóò di èyí tí a gbé ga, òun yóò sì mú ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá ṣubú ní ti gidi; ṣùgbọ́n kì yóò lo ipò alágbára rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 11:12) Ẹgbàárùn-ún ọmọ ogun tí ń fẹsẹ̀ rìn àti ọ̀ọ́dúnrún agẹṣinjagun ni Pẹ́tólẹ́mì Kẹrin pa dànù lára ọmọ ogun Síríà, ó sì “kó” ẹgbàajì “lọ” lóǹdè. Ọba méjèèjì wá ṣe àdéhùn tí ó jẹ́ kí Séléúkíà tí ó jẹ́ ibùdókọ̀ òkun ti Síríà máa bá a lọ láti jẹ́ ti Áńtíókọ́sì Kẹta, àmọ́, ó pàdánù Foníṣíà àti Koele ti Síríà. Nítorí bí ọba gúúsù ti Íjíbítì ṣe ṣẹ́gun yìí, ọkàn-àyà rẹ̀ ‘di èyí tí ó gbé ga,’ pàápàá sí Jèhófà. Júdà ń bá a lọ láti wà lábẹ́ ìdarí Pẹ́tólẹ́mì Kẹrin. Àmọ́, kò “lo ipò alágbára rẹ̀” láti fi máa báṣẹ́ nìṣó lórí ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí ọba àríwá ti Síríà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbé ayé oníwọ̀bìà ni Pẹ́tólẹ́mì Kẹrin lọ ń gbé, ọmọ rẹ̀ Pẹ́tólẹ́mì Karùn-ún, tí ó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún, sì di ọba gúúsù tí ó jẹ tẹ̀ lé e fún ọdún mélòó kan kí Áńtíókọ́sì Kẹta tó kú.
AKÓNI-NÍFÀ PADÀ WÁ
27. Báwo ni ọba àríwá ṣe padà wá ní “òpin àkókò náà” láti gba àwọn ìpínlẹ̀ padà ní ilẹ̀ Íjíbítì?
27 Nítorí gbogbo ìwà akin tí Áńtíókọ́sì Kẹta ní, ó di ẹni tí a pè ní Áńtíókọ́sì Ńlá. Áńgẹ́lì náà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé: “Ọba àríwá yóò sì padà, yóò sì kó ogunlọ́gọ̀ jọ tí ó pọ̀ ju ti àkọ́kọ́; àti lẹ́yìn òpin àkókò náà, ní ọdún mélòó kan, yóò dé, ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ológun ńláǹlà àti pẹ̀lú ẹrù púpọ̀ rẹpẹtẹ.” (Dáníẹ́lì 11:13) “Àkókò” yẹn jẹ́ ọdún mẹ́rìndínlógún tàbí kí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, lẹ́yìn tí àwọn ará Íjíbítì ṣẹ́gun àwọn ará Síríà ní ìlú Ráfíà. Nígbà tí ọ̀dọ́mọdé náà, Pẹ́tólẹ́mì Karùn-ún, di ọba gúúsù, Áńtíókọ́sì Kẹta bá gbéra tòun ti ‘ogunlọ́gọ̀ tí ó pọ̀ ju ti àkọ́kọ́’ lọ láti lè gba àwọn ìpínlẹ̀ tí ó ti ọwọ́ rẹ̀ bọ́ sọ́wọ́ ọba gúúsù ti Íjíbítì, padà. Látàrí èyí, ó pa agbo ọmọ ogun rẹ̀ pọ̀ mọ́ ti Fílípì Karùn-ún, ọba Makedóníà.
28. Ìjàngbọ̀n wo ni ọ̀dọ́mọdé ọba gúúsù kò?
28 Ọba gúúsù tún ko ìjàngbọ̀n pẹ̀lú nínú ìjọba rẹ̀. Áńgẹ́lì náà sọ pé: “Ní àkókò wọnnì, ọ̀pọ̀ yóò dìde sí ọba gúúsù.” (Dáníẹ́lì 11:14a) “Ọ̀pọ̀ . . . dìde sí ọba gúúsù” lóòótọ́. Yàtọ̀ sí ti pé ó dojú kọ agbo ọmọ ogun Áńtíókọ́sì Kẹta, àti àwọn ará Makedóníà tí ó dara pọ̀ mọ́ wọn, ọba gúúsù tí ó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ náà tún ko ìṣòro ní ilẹ̀ rẹ̀ ní Íjíbítì. Agatókù olùtọ́jú rẹ̀, tí ó ń fi orúkọ rẹ̀ ṣàkóso, ń hùwà ìgbéraga sí àwọn ará Íjíbítì, bí púpọ̀ nínú wọn ṣe fárí gá nìyẹn. Áńgẹ́lì náà fi kún un pé: “Ní tiwọn, àwọn ọmọ ọlọ́ṣà tí ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn rẹ ni a óò gbé lọ nínú ìgbìyànjú láti mú kí ìran kan ní ìmúṣẹ; wọn yóò sì kọsẹ̀.” (Dáníẹ́lì 11:14b) Kódà, díẹ̀ lára àwọn ènìyàn Dáníẹ́lì di “àwọn ọmọ ọlọ́ṣà” tàbí olùlépa ìyípadà tipátipá. Ṣùgbọ́n “ìran” èyíkéyìí tí irú àwọn Júù bẹ́ẹ̀ lè rí nípa ti mímú kí ìṣàkóso àwọn Kèfèrí kásẹ̀ ní ìlú ìbílẹ̀ wọn, jẹ́ èké, wọn yóò sì kùnà, tàbí pé wọn yóò “kọsẹ̀.”
29, 30. (a) Báwo ni “apá gúúsù” ṣe ṣubú níwájú àwọn ọmọ ogun àríwá? (b) Báwo ni ọba àríwá ṣe wá “dúró ní ilẹ̀ Ìṣelóge”?
29 Áńgẹ́lì Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ síwájú sí i pé: “Ọba àríwá yóò sì wá, yóò sì yára kọ́ ohun àfiṣe-odi ìsàgatì kan, yóò sì gba ìlú ńlá tí ó ní odi ní ti gidi. Àti ní ti apá gúúsù, wọn kì yóò dúró, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn ààyò rẹ̀; kì yóò sì sí agbára láti dúró. Ẹni tí ó sì ń bọ̀ láti gbéjà kò ó yóò ṣe ìfẹ́ ara rẹ̀, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dúró níwájú rẹ̀. Yóò sì dúró ní ilẹ̀ Ìṣelóge, ìparun pátápátá yóò sì wà ní ọwọ́ rẹ̀.”—Dáníẹ́lì 11:15, 16.
30 Agbo ọmọ ogun tí ó wà lábẹ́ Pẹ́tólẹ́mì Karùn-ún, tàbí “apá gúúsù,” ṣubú níwájú àwọn ọmọ ogun àríwá. Ní Pánéà (Kesaréà ti Fílípì), Áńtíókọ́sì Kẹta lé Ọ̀gágun Síkópà ti Íjíbítì àti ẹgbàárùn-ún àṣàyàn ènìyàn, tàbí “àwọn ènìyàn ààyò,” wọ ìlú Sídónì, “ìlú ńlá tí ó ní odi.” Áńtíókọ́sì Kẹta “kọ́ ohun àfiṣe-odi ìsàgatì kan” síbẹ̀, ó sì gba ibùdókọ̀ òkun ilẹ̀ Foníṣíà yẹn ní ọdún 198 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ó “ṣe ìfẹ́ ara rẹ̀,” nítorí agbo ọmọ ogun ọba Íjíbítì tí í ṣe ọba gúúsù kò lè dúró níwájú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Áńtíókọ́sì Kẹta lọ gbé ogun ja Jerúsálẹ́mù, olú ìlú Júdà, “ilẹ̀ Ìṣelóge” náà. Lọ́dún 198 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jerúsálẹ́mù àti Júdà kúrò lábẹ́ àkóso ọba gúúsù ti ilẹ̀ Íjíbítì, ó sì bọ́ sábẹ́ ọba àríwá ti Síríà. Áńtíókọ́sì Kẹta, ọba àríwá bá “dúró ní ilẹ̀ Ìṣelóge.” ‘Ìparun pátápátá sì wà ní ọwọ́ rẹ̀’ fún àwọn Júù tàbí ará Íjíbítì tí ó bá takò ó. Báwo ni ọba àríwá yìí yóò ṣe ṣe ìfẹ́ ara rẹ̀ pẹ́ tó?
RÓÒMÙ KÁ AKÓNI-NÍFÀ LỌ́WỌ́ KÒ
31, 32. Èé ṣe tí ọba àríwá fi wá bá ọba gúúsù ṣe “àdéhùn ìfẹ̀tọ́-bánilò-lọ́gbọọgba” nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín?
31 Áńgẹ́lì Jèhófà dá wa lóhùn pé: “[Ọba àríwá] yóò sì fi ojú Dáníẹ́lì 11:17.
sí wíwá pẹ̀lú ipá alágbára ti gbogbo ìjọba rẹ̀ pátá, yóò sì ní àdéhùn ìfẹ̀tọ́-bánilò-lọ́gbọọgba; yóò sì gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́. Ní ti ọmọbìnrin ẹ̀dá obìnrin, a ó yọ̀ǹda fún ọkùnrin náà láti run ún. Obìnrin náà kì yóò dúró, kì yóò jẹ́ ti ọkùnrin náà mọ́.”—32 Áńtíókọ́sì Kẹta, ọba àríwá, “fi ojú sí” ṣíṣàkóso ilẹ̀ Íjíbítì “pẹ̀lú ipá alágbára ti gbogbo ìjọba rẹ̀ pátá.” Àmọ́, “àdéhùn ìfẹ̀tọ́-bánilò-lọ́gbọọgba” ni ó bá Pẹ́tólẹ́mì Karùn-ún, ọba gúúsù, ṣe nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Ohun tí ilẹ̀ Róòmù ní kí Áńtíókọ́sì Kẹta ṣe ti mú kí ó yí ìwéwèé rẹ̀ padà. Nígbà tí òun àti Ọba Fílípì Karùn-ún ti Makedóníà lẹ̀dí àpò pọ̀ láti gbéjà ko ọba Íjíbítì tí ó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé, kí wọ́n lè gba àwọn ìpínlẹ̀ rẹ̀, àwọn olùtọ́jú Pẹ́tólẹ́mì Karùn-ún bá yíjú sí ilẹ̀ Róòmù fún ààbò. Ilẹ̀ Róòmù fẹ́ lo àǹfààní yẹn láti mú kí ibi tí agbára rẹ̀ dé gbòòrò sí i, nítorí náà, ó bá halẹ̀ kàràkàrà.
33. (a) Kí ní ń bẹ nínú àdéhùn àlàáfíà tí Áńtíókọ́sì Kẹta àti Pẹ́tólẹ́mì Karùn-ún jùmọ̀ ṣe? (b) Kí ni ète ìgbéyàwó láàárín Kilẹopátírà Kìíní àti Pẹ́tólẹ́mì Karùn-ún, èé sì ti ṣe tí ète náà fi kùnà?
33 Nítorí pé ilẹ̀ Róòmù mú Áńtíókọ́sì Kẹta ní dandangbọ̀n, ó bá ọba gúúsù ṣe àdéhùn àlàáfíà. Àmọ́, dípò tí Áńtíókọ́sì Kẹta ì bá fi jọ̀wọ́ àwọn ìpínlẹ̀ tí ó ti ṣẹ́gun gẹ́gẹ́ bí Róòmù ṣe sọ, ó pète láti kàn fẹnu sọ pé òun ti jọ̀wọ́ rẹ̀, ní ti pé ó mú kí ọmọbìnrin rẹ̀ Kilẹopátírà Kìíní—“ọmọbìnrin ẹ̀dá obìnrin”—lọ fẹ́ Pẹ́tólẹ́mì Karùn-ún. Àwọn ìpínlẹ̀ kan títí kan Júdà, “ilẹ̀ Ìṣelóge,” sì ni ọmọbìnrin náà fi fún ọkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí nǹkan àna. Àmọ́, nígbà ìgbéyàwó wọn lọ́dún 193 ṣááju Sànmánì Tiwa, ọba Síríà kò yọ̀ǹda ìpínlẹ̀ wọ̀nyí fún Pẹ́tólẹ́mì Karùn-ún. Ìgbéyàwó lọ́nà ti ìṣèlú ni èyí jẹ́, ó ṣe bẹ́ẹ̀ láti mú kí Íjíbítì bọ́ sábẹ́ Síríà. Ṣùgbọ́n ète tí ó pa kùnà, nítorí pé Kilẹopátírà Kìíní kò “jẹ́ ti ọkùnrin náà mọ́,” nítorí ẹ̀yìn ọkọ rẹ̀ ni ó gbè sí. Nígbà tí ogun bẹ́ sílẹ̀ láàárín Áńtíókọ́sì Kẹta àti àwọn ará Róòmù, ìhà àwọn ará Róòmù ni Íjíbítì wà.
34, 35. (a) Àwọn “ilẹ̀ etí òkun” wo ni ọba àríwá yíjú sí? (b) Báwo ni Róòmù ṣe mú òpin dé bá “ẹ̀gàn” tí ọba àríwá fẹ́ mú bá a? (d) Báwo ni Áńtíókọ́sì Kẹta ṣe kú, ta sì ni ó wá dí ọba àríwá lẹ́yìn rẹ̀?
34 Áńgẹ́lì náà sọ nípa bí ọba àríwá ṣe máa padà sẹ́yìn, ní fífikún un pé: “[Áńtíókọ́sì Kẹta] yóò sì yí ojú rẹ̀ padà sí ilẹ̀ etí òkun, yóò sì kó ọ̀pọ̀ ní ti gidi. Ọ̀gágun kan [Róòmù] yóò sì ní láti mú kí ẹ̀gàn rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀ fún ara rẹ̀ [Róòmù], kí ẹ̀gàn rẹ̀ [tó tọwọ́ Áńtíókọ́sì Kẹta wá] má bàa sí mọ́. [Róòmù] yóò mú kí ó yí padà sórí ẹni yẹn. [Áńtíókọ́sì Kẹta] yóò sì yí ojú rẹ̀ padà sí odi agbára ilẹ̀ tirẹ̀ fúnra rẹ̀, òun yóò sì kọsẹ̀, yóò sì ṣubú, a kì yóò sì rí i.”—35 Àwọn “ilẹ̀ etí òkun” wọ̀nyẹn ni ti Makedóníà, Gíríìsì àti ti Éṣíà Kékeré. Ogun kan bẹ́ sílẹ̀ ní Gíríìsì lọ́dún 192 ṣááju Sànmánì Tiwa, èyí mú kí Áńtíókọ́sì Kẹta wá sí ilẹ̀ Gíríìsì. Bí ọba Síríà yìí ṣe gbìyànjú láti tún gba ìpínlẹ̀ sí i níbẹ̀ bí ilẹ̀ Róòmù nínú, ló bá kúkú kéde ogun sí i. Àwọn ará Róòmù ṣẹ́gun rẹ̀ ní Tamopílè. Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tí a ṣẹ́gun rẹ̀ nínú ogun Maginésíà lọ́dún 190 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó di dandan pé kí ó jọ̀wọ́ gbogbo Gíríìsì pátá àti Éṣíà Kékeré, àti àwọn àgbègbè tí ó wà ní ìwọ̀-oòrùn àwọn Òkè Táúrù. Ìtanràn ńlá ni ilẹ̀ Róòmù bù lé e lórí, Róòmù sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso ọba àríwá ti Síríà. Níwọ̀n bí a ti lé Áńtíókọ́sì Kẹta kúrò ní Gíríìsì àti Éṣíà Kékeré, tí ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pàdánù gbogbo ọkọ̀ òkun rẹ̀ pátá, ó bá “yí ojú rẹ̀ padà sí” Síríà, “odi agbára ilẹ̀ tirẹ̀ fúnra rẹ̀.” Àwọn ará Róòmù ‘yí ẹ̀gàn tí ó fẹ́ mú bá wọn padà sórí òun fúnra rẹ̀.’ Áńtíókọ́sì Kẹta kú nígbà tí ó ń gbìyànjú láti jí tẹ́ńpìlì kan kó ní ìlú Élímáísì ti ilẹ̀ Páṣíà, lọ́dún 187 ṣááju Sànmánì Tiwa. Bí ó ṣe “ṣubú” nípa kíkú nìyẹn, tí ọmọ rẹ̀ Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kẹrin, ọba àríwá tí ó kàn, sì rọ́pò rẹ̀.
GÍDÍGBÒ NÁÀ Ń BÁ A LỌ
36. (a) Báwo ni ọba gúúsù ṣe fẹ́ máa bá ìjàkadì náà lọ, ṣùgbọ́n kí ní ṣẹlẹ̀ sí i? (b) Báwo ni Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kẹrin ṣe ṣubú, ta ló sì rọ́pò rẹ̀?
36 Pẹ́tólẹ́mì Karùn-ún, gẹ́gẹ́ bí ọba gúúsù, gbìyànjú láti
gba àwọn ìpínlẹ̀ tí ó yẹ kí ó di tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdána tí a san lórí Kilẹopátírà, ṣùgbọ́n a gbé májèlé fún un jẹ. Pẹ́tólẹ́mì Kẹfà wá rọ́pò rẹ̀. Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kẹrin ńkọ́? Bí ó ṣe ń wá owó tí yóò fi san ìtanràn ńlá tí ilẹ̀ Róòmù bù lé e, ó rán Hẹliódórù akápò rẹ̀ lọ kó àwọn ìṣúra tí a sọ pé a tọ́jú pa mọ́ sínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Bí Hẹliódórù náà ti fẹ́ gorí ìtẹ́, ó bá pa Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kẹrin. Àmọ́, Yúménésì ọba Pẹ́gámọ́mù àti arákùnrin rẹ̀, Átálúsì Ọba, gbé Áńtíókọ́sì Kẹrin, arákùnrin ọba tí a pa náà, gorí ìtẹ́.37. (a) Báwo ni Áńtíókọ́sì Kẹrin ṣe gbìyànjú láti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni tí ó lágbára ju Jèhófà Ọlọ́run lọ? (b) Kí ni ìsọdàìmọ́ tí Áńtíókọ́sì Kẹrin ṣe sí tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù yọrí sí?
37 Áńtíókọ́sì Kẹrin, ọba àríwá tuntun, wọ́nà láti fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó lágbára ju Ọlọ́run lọ nípa sísapá láti fòpin sí ìṣètò tí Jèhófà ṣe fún jíjọ́sìn. Ní fífojú tín-ínrín Jèhófà, ó ya tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù sí mímọ́ fún Súúsì, tàbí Júpítà. Ní oṣù December ọdún 167 ṣááju Sànmánì Tiwa, a mọ pẹpẹ abọ̀rìṣà sórí pẹpẹ ńlá ti inú àgbàlá tẹ́ńpìlì, níbi tí a ti ń rú ẹbọ sísun ojoojúmọ́ sí Jèhófà tẹ́lẹ̀. Ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn náà, a rú ẹbọ sí Súúsì lórí pẹpẹ abọ̀rìṣà náà. Ìsọdàìmọ́ yìí ló fà á tí àwọn Júù fi gbógun dìde lábẹ́ ìdarí àwọn Mákábì. Ọdún mẹ́ta ni Áńtíókọ́sì Kẹrin fi bá wọn jà. Lọ́dún 164 ṣááju Sànmánì Tiwa, ní àyájọ́ ìgbà ìsọdàìmọ́ náà, Júdásì Mákábíọ́sì tún tẹ́ńpìlì náà yà sí mímọ́ sí Jèhófà, a sì dá àjọyọ̀ ìyàsímímọ́—Hánúkà—sílẹ̀.—Jòhánù 10:22.
38. Báwo ni ìṣàkóso àwọn Mákábì ṣe dópin?
38 Ó dà bíi pé àwọn Mákábì bá ilẹ̀ Róòmù ṣe àdéhùn ní ọdún 161 ṣááju Sànmánì Tiwa, wọ́n sì gbé ìjọba kalẹ̀ ní ọdún 104 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n, gbọ́nmi-sí omi-ò-to ń bá a lọ láàárín àwọn àti ọba Síríà. Níkẹyìn, wọ́n pe Róòmù láti wá dá sí i. Ọ̀gágun Gínéọ́sì Pọ́ńpè, ará Róòmù, gba Jerúsálẹ́mù lọ́dún 63 ṣááju Sànmánì Tiwa lẹ́yìn gbígbógun tì í fún oṣù mẹ́ta. Lọ́dún 39 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ilé Aṣòfin Àgbà ní Róòmù fi Hẹ́rọ́dù—ará Édómù—jẹ ọba
Jùdíà. Ó fòpin sí ìṣàkóso àwọn Mákábì, ó sì gba Jerúsálẹ́mù lọ́dún 37 ṣááju Sànmánì Tiwa.39. Báwo ni o ti ṣe jàǹfààní láti inú ṣíṣe àgbéyẹ̀wò Dáníẹ́lì 11:1-19?
39 Ó mà wúni lórí o, láti rí bí apá àkọ́kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọba méjì tí wọ́n wọ gídígbò ṣe ní ìmúṣẹ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́! Ní tòótọ́, ìwúrí gidi ni ó mà jẹ́ fúnni o, pé a lè bojú wo ìtàn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún lẹ́yìn tí a ti sọ ìhìn iṣẹ́ alásọtẹ́lẹ̀ náà fún Dáníẹ́lì, kí a sì dá àwọn ọba tí ó wà ní ipò ọba àríwá àti ọba gúúsù mọ̀! Àmọ́ ṣá, ọ̀ràn ìṣèlú tí a fi ń dá àwọn ọba méjèèjì wọ̀nyí mọ̀ yí padà bí ogun àárín wọn ṣe ń bá a nìṣó ré kọjá ìgbà tí Jésù Kristi gbé láyé títí di ìgbà tiwa lónìí. Nípa fífi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìtàn wéra pẹ̀lú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ fífaní lọ́kàn mọ́ra tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣí payá, yóò ṣeé ṣe fún wa láti mọ àwọn ọba méjèèjì tí ń figa gbága yìí.
KÍ LO LÓYE?
• Ìlà àwọn ọba alágbára méjì wo ni ó jẹyọ láti inú àwọn ìjọba Hélénì, ìjàkadì wo ni àwọn ọba náà sì bẹ̀rẹ̀?
• Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 11:6, báwo ni ọba méjèèjì náà ṣe wọnú “àdéhùn ìfẹ̀tọ́-bánilò-lọ́gbọọgba”?
• Báwo ni gídígbò náà ṣe lọ láàárín
Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kejì àti Pẹ́tólẹ́mì Kẹta (Dáníẹ́lì 11:7-9)?
Áńtíókọ́sì Kẹta àti Pẹ́tólẹ́mì Kẹrin (Dáníẹ́lì 11:10-12)?
Áńtíókọ́sì Kẹta àti Pẹ́tólẹ́mì Karùn-ún (Dáníẹ́lì 11:13-16)?
• Kí ni ète ìgbéyàwó láàárín Kilẹopátírà Kìíní àti Pẹ́tólẹ́mì Karùn-ún, kí sì ni ìdí tí ìpète yẹn fi kùnà? (Dáníẹ́lì 11:17-19)?
• Báwo ni kíkíyèsí Dáníẹ́lì 11:1-19 ṣe ṣàǹfààní fún ọ?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àtẹ Ìsọfúnnni\Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 228]
ÀWỌN ỌBA INÚ ÌWÉ DÁNÍẸ́LÌ 11:5-19
Ọba Àríwá Ọba Gúúsù
Dáníẹ́lì 11:5 Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní Níkétọ̀ Pẹ́tólẹ́mì Kìíní
Dáníẹ́lì 11:6 Áńtíókọ́sì Kejì Pẹ́tólẹ́mì Kejì
(aya rẹ̀ ni Laodísì) (ọmọbìnrin rẹ̀ ni
Béréníkè)
Dáníẹ́lì 11:7-9 Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kejì Pẹ́tólẹ́mì Kẹta
Dáníẹ́lì 11:10-12 Áńtíókọ́sì Kẹta Pẹ́tólẹ́mì Kẹrin
Dáníẹ́lì 11:13-19 Áńtíókọ́sì Kẹta Pẹ́tólẹ́mì Karùn-ún
(Ọmọbìnrin rẹ̀ ni
Kilẹopátírà Kìíní) Arọ́pò rẹ̀:
Àwọn arọ́pò rẹ̀: Pẹ́tólẹ́mì Kẹfà
Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kẹrin àti
Áńtíókọ́sì Kẹrin
[Àwòrán]
Owó tí a yàwòrán Pẹ́tólẹ́mì Kejì àti aya rẹ̀ sí
[Àwòrán]
Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní Níkétọ̀
[Àwòrán]
Áńtíókọ́sì Kẹta
[Àwòrán]
Pẹ́tólẹ́mì Kẹfà
[Àwòrán]
Pẹ́tólẹ́mì Kẹta àti àwọn arọ́pò rẹ̀ ni wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì yìí fún Hórúsì ní ìlú Ídífù, ní Íjíbítì Òkè
[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 216, 217]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Àwọn orúkọ náà, “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” tọ́ka sí àwọn ọba tó wà ní àríwá àti gúúsù ilẹ̀ àwọn ènìyàn Dáníẹ́lì
MAKEDÓNÍÀ
GÍRÍÌSÌ
ÉṢÍÀ KÉKERÉ
ÍSÍRẸ́LÌ
LÍBÍÀ
ÍJÍBÍTÌ
ETIÓPÍÀ
SÍRÍÀ
Bábílónì
ARÉBÍÀ
[Àwòrán]
Pẹ́tólẹ́mì Kejì
[Àwòrán]
Áńtíókọ́sì Ńlá
[Àwòrán]
Òkúta fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kan tí a kọ àwọn àṣẹ ọba tí Áńtíókọ́sì Ńlá pa sí
[Àwòrán]
Owó tí a yàwòrán Pẹ́tólẹ́mì Karùn-ún sí
[Àwòrán]
Ẹnubodè Pẹ́tólẹ́mì Kẹta ní ìlú Karnak ní Íjíbítì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 210]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 215]
Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní Níkétọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 218]
Pẹ́tólẹ́mì Kìíní