Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Ṣí Àkókò Dídé Mèsáyà Payá

A Ṣí Àkókò Dídé Mèsáyà Payá

Orí Kọkànlá

A Ṣí Àkókò Dídé Mèsáyà Payá

1. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Jèhófà ni Olùpàkókòmọ́ Gíga Jù, kí ló lè dá wa lójú?

JÈHÓFÀ ni Olùpàkókòmọ́ Ńlá náà. Abẹ́ àkóso rẹ̀ ni gbogbo ìgbà àti àkókò tí ó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rẹ̀ wà. (Ìṣe 1:7) Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti fi sí ìgbà àti àkókò wọ̀nyí yóò ṣẹ dájúdájú. Wọn kì yóò kùnà.

2, 3. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Dáníẹ́lì yí àfiyèsí sí, ilẹ̀ ọba wo sì ni ó ń ṣàkóso Bábílónì nígbà yẹn?

2 Níwọ̀n bí wòlíì Dáníẹ́lì ti jẹ́ aláápọn nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, ó nígbàgbọ́ pé Jèhófà lè ṣètòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kí ó sì mú kí wọ́n ṣẹlẹ̀. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìsọdahoro Jerúsálẹ́mù ni ó gbàfiyèsí Dáníẹ́lì ní pàtàkì. Jeremáyà ti ṣàkọsílẹ̀ ohun tí Ọlọ́run ṣí payá nípa bí ìlú mímọ́ náà yóò ṣe wà ní ahoro pẹ́ tó, àsọtẹ́lẹ̀ yìí sì ni Dáníẹ́lì gbé yẹ̀ wò kínníkínní. Ó kọ̀wé pé: “Ní ọdún kìíní Dáríúsì ọmọkùnrin Ahasuwérúsì, tí ó jẹ́ irú-ọmọ àwọn ará Mídíà, ẹni tí a ti fi jẹ ọba lórí ìjọba àwọn ará Kálídíà; ní ọdún kìíní ìgbà ìjọba rẹ̀, èmi fúnra mi, Dáníẹ́lì, fi òye mọ̀ láti inú ìwé, iye ọdún nípa èyí tí ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Jeremáyà wòlíì wá, láti mú ìparundahoro Jerúsálẹ́mù ṣẹ, èyíinì ni, àádọ́rin ọdún.”—Dáníẹ́lì 9:1, 2; Jeremáyà 25:11.

3 Dáríúsì ará Mídíà ní ń ṣàkóso lórí “ìjọba àwọn ará Kálídíà” nígbà yẹn. Ohun tí Dáníẹ́lì ti sọ tẹ́lẹ̀ níṣàájú, nígbà tí ó ń túmọ̀ ìkọ̀wé ara ògiri, ti ní ìmúṣẹ kíákíá. Ilẹ̀ Ọba Bábílónì kò sí mọ́. A ti fi í fún “àwọn ará Mídíà àti Páṣíà” ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa.—Dáníẹ́lì 5:24-28, 30, 31.

DÁNÍẸ́LÌ BẸ JÈHÓFÀ TÌRẸ̀LẸ̀-TÌRẸ̀LẸ̀

4. (a) Kí ló ń béèrè kí Ọlọ́run tó lè dá wọn nídè? (b) Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe wá tọ Jèhófà lọ?

4 Dáníẹ́lì mọ̀ pé ìdahoro Jerúsálẹ́mù fún àádọ́rin ọdún ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin. Kí ló kàn tí yóò ṣe? Òun fúnra rẹ̀ sọ fún wa pé: “Mo sì ń bá a lọ láti kọjú mi sí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, láti lè wá a pẹ̀lú àdúrà àti pẹ̀lú ìpàrọwà, pẹ̀lú ààwẹ̀ gbígbà àti aṣọ àpò ìdọ̀họ àti eérú. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run mi, mo sì jẹ́wọ́.” (Dáníẹ́lì 9:3, 4) Ó ń béèrè ipò ọkàn títọ́ láti lè rí ìdáǹdè aláàánú gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Léfítíkù 26:31-46; 1 Àwọn Ọba 8:46-53) Ó ń béèrè ìgbàgbọ́, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, àti ìrònúpìwàdà délẹ̀délẹ̀ lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sọ wọ́n dèrò ìgbèkùn àti ẹrú. Nítorí náà, Dáníẹ́lì wá tọ Ọlọ́run lọ ní tìtorí àwọn ènìyàn rẹ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀. Báwo? Nípa pé ó gba ààwẹ̀, ó ṣọ̀fọ̀, ó sì wọ aṣọ àpò ìdọ̀họ, tí ó jẹ́ àmì ìrònúpìwàdà àti òtítọ́ ọkàn.

5. Kí ní jẹ́ kí Dáníẹ́lì lè ní ìdánilójú pé a óò dá àwọn Júù padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn?

5 Àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà mú kí Dáníẹ́lì nírètí, nítorí ó fi hàn pé a óò mú àwọn Júù padà bọ̀ sí ìlú ìbílẹ̀ wọn ní Júdà láìpẹ́. (Jeremáyà 25:12; 29:10) Láìsí iyèméjì, ó dá Dáníẹ́lì lójú pé ìtura yóò débá àwọn Júù tí a tẹ̀ lórí ba nítorí pé ẹnì kan tí a ń pè ní Kírúsì ti di ọba lórí Páṣíà. Aísáyà kò ha ti sọ tẹ́lẹ̀ bí, pé Kírúsì yóò kó ipa pàtàkì nínú bí a óò ṣe dá àwọn Júù sílẹ̀ lómìnira kí wọ́n lè lọ tún Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì kọ́? (Aísáyà 44:28–45:3) Ṣùgbọ́n Dáníẹ́lì kò mọ bí èyí yóò ṣe wáyé gan-an. Nítorí náà, ó ń bá a lọ láti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà.

6. Nínú àdúrà Dáníẹ́lì àwọn nǹkan wo ni ó gbà pé ó ṣẹlẹ̀?

6 Dáníẹ́lì pe àfiyèsí sí àánú Ọlọ́run àti inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́. Ó gbà tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ pé àwọn Júù ṣẹ̀ nípa pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀, tí wọ́n yà kúrò nínú àwọn òfin Jèhófà, tí wọ́n sì ṣàìka àwọn wòlíì rẹ̀ sí. Bí Ọlọ́run ṣe ‘fọ́n wọn ká nítorí ìwà àìṣòótọ́ tí wọ́n hù’ tọ́ sí wọn. Dáníẹ́lì gbàdúrà pé: “Jèhófà, tiwa ni ìtìjú, ti àwọn ọba wa, àwọn ọmọ aládé wa àti àwọn baba ńlá wa, nítorí a ti ṣẹ̀ sí ọ. Ti Jèhófà Ọlọ́run wa ni àánú àti ìṣe ìdáríjì, nítorí a ti ṣọ̀tẹ̀ sí i. A kò sì ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa nípa rírìn nínú òfin rẹ̀ tí ó gbé ka iwájú wa láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, wòlíì. Gbogbo Ísírẹ́lì sì ti tẹ òfin rẹ lójú, yíyà kúrò sì ti ṣẹlẹ̀ nípa ṣíṣàìgbọràn sí ohùn rẹ, tí o fi da ègún àti ìbúra tí a kọ sínú òfin Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ jáde sórí wa, nítorí a ti ṣẹ̀ sí I.”—Dáníẹ́lì 9:5-11; Ẹ́kísódù 19:5-8; 24:3, 7, 8.

7. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé ohun tí Jèhófà ṣe tọ́ ní ti bí ó ṣe gbà kí àwọn Júù lọ sí ìgbèkùn?

7 Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣáájú nípa ohun tí yóò yọrí sí bí wọ́n bá ṣàìgbọràn sí òun tí wọn kò sì ka májẹ̀mú tí òun bá wọn dá sí. (Léfítíkù 26:31-33; Diutarónómì 28:15; 31:17) Dáníẹ́lì gbà pé àwọn ìgbésẹ̀ tí Ọlọ́run gbé tọ̀nà, ó wí pé: “Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó ti sọ lòdì sí wa àti lòdì sí àwọn onídàájọ́ tí ń ṣe ìdájọ́ wa ṣẹ, nípa mímú ìyọnu àjálù ńláǹlà wá sórí wa, irú èyí tí a kò ṣe lábẹ́ gbogbo ọ̀run bí èyí tí a ṣe ní Jerúsálẹ́mù. Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Mósè, gbogbo ìyọnu àjálù yìí—ó ti dé sórí wa, a kò sì tu ojú Jèhófà Ọlọ́run wa nípa yíyípadà kúrò nínú ìṣìnà wa àti nípa fífi ìjìnlẹ̀ òye hàn nínú òótọ́ rẹ. Jèhófà sì wà lójúfò sí ìyọnu àjálù náà, ó sì mú un wá sórí wa níkẹyìn, nítorí Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ olódodo nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ṣe; a kò sì ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀.”—Dáníẹ́lì 9:12-14.

8. Orí kí ni Dáníẹ́lì gbé ẹ̀bẹ̀ tí ó ń bẹ Jèhófà kà?

8 Dáníẹ́lì kò wọ́nà láti dá àwọn ìgbésẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ láre. Lílọ tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn tọ́ sí wọn, gan-an bí ó ṣe sọ ní ṣàkó pé: “A ti ṣẹ̀, a ti ṣe ohun burúkú.” (Dáníẹ́lì 9:15) Ohun tí ó jẹ ẹ́ lógún tayọ kìkì rírí ìtura gbà kúrò nínú ìjìyà wọn. Rárá o, orí ògo àti ọlá Jèhófà gan-an ni ó gbé ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ kà. Bí Ọlọ́run bá dárí ji àwọn Júù tí ó sì dá wọn padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, a jẹ́ pé ó mú ìlérí tí ó ṣe nípasẹ̀ Jeremáyà ṣẹ, tí yóò sì sọ orúkọ Rẹ̀ di mímọ́. Dáníẹ́lì jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pé: “Jèhófà, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ìṣe òdodo rẹ, jọ̀wọ́, kí ìbínú rẹ àti ìhónú rẹ yí padà kúrò lọ́dọ̀ ìlú ńlá rẹ, Jerúsálẹ́mù, òkè ńlá mímọ́ rẹ; nítorí, fún ẹ̀ṣẹ̀ wa àti ìṣìnà àwọn baba ńlá wa, Jerúsálẹ́mù àti àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ohun ẹ̀gàn lójú gbogbo àwọn tí ó yí wa ká.”—Dáníẹ́lì 9:16.

9. (a) Àwọn àrọwà wo ni Dáníẹ́lì fi parí àdúrà rẹ̀? (b) Kí ní kó ìdààmú bá Dáníẹ́lì, ṣùgbọ́n báwo ni ó ṣe bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run?

9 Dáníẹ́lì ń gba àdúrà kíkankíkan lọ pé: “Wàyí o, Ọlọ́run wa, fetí sílẹ̀, sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti sí ìpàrọwà rẹ̀, sì jẹ́ kí ojú rẹ tàn sára ibùjọsìn rẹ tí a sọ di ahoro, nítorí ti Jèhófà. Ọlọ́run mi, dẹ etí sílẹ̀, kí o sì gbọ́. La ojú rẹ kí o sì rí ipò ahoro wa àti ìlú ńlá tí a fi orúkọ rẹ pè; nítorí kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìṣe òdodo wa ni a ń jẹ́ kí ìpàrọwà wa wá síwájú rẹ, bí kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àánú rẹ. Sáà gbọ́, Jèhófà. Sáà dárí jì, Jèhófà. Sáà fetí sílẹ̀ kí o sì gbé ìgbésẹ̀, Jèhófà. Má ṣe jáfara, nítorí tìrẹ, Ọlọ́run mi, nítorí orúkọ rẹ ni a fi pe ìlú ńlá rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ.” (Dáníẹ́lì 9:17-19) Bí Ọlọ́run bá kọ̀ láti dárí jì, tí ó sì fi àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ ní ìgbèkùn, tí ó fi Jerúsálẹ́mù ìlú mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀ láhoro títí lọ, àwọn orílẹ̀-èdè yóò ha gbà pé ó jẹ́ Ọba Aláṣẹ Àgbáyé bí? Wọn kò ha ní wí pé ńṣe ni apá Jèhófà kò ká àwọn ọlọ́run Bábílónì? Bẹ́ẹ̀ ni o, yóò kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà, èyí sì kó ìdààmú bá Dáníẹ́lì. Nínú ìgbà mọ́kàndínlógún tí Jèhófà, orúkọ Ọlọ́run, fara hàn nínú ìwé Dáníẹ́lì, ìgbà méjìdínlógún ló bá àdúrà yìí lọ!

GÉBÚRẸ́LÌ DÉ KÍÁKÍÁ

10. (a) Ta ni a rán sí Dáníẹ́lì kíákíá, èé sì ti ṣe? (b) Èé ṣe tí Dáníẹ́lì fi lo “ọkùnrin” fún Gébúrẹ́lì?

10 Dáníẹ́lì ṣì ń gbàdúrà lọ́wọ́ ni áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì bá yọ sí i. Ó sọ pé: “Ìwọ Dáníẹ́lì, nísinsìnyí mo wá láti mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye pẹ̀lú ìmọ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìpàrọwà rẹ, ọ̀rọ̀ kan jáde lọ, èmi fúnra mi sì wá láti ròyìn, nítorí o jẹ́ ẹnì kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi. Nítorí náà, gba ọ̀ràn náà yẹ̀ wò, sì ní òye nínú ohun tí o rí.” Àmọ́, èé ṣe tí Dáníẹ́lì fi pè é ní “ọkùnrin náà Gébúrẹ́lì”? (Dáníẹ́lì 9:20-23) Tóò, nígbà tí Dáníẹ́lì ń fẹ́ láti mòye ìran tí ó rí níṣàájú, nípa akọ ewúrẹ́ àti àgbò, “ẹnì kan tí ó ní ìrísí abarapá ọkùnrin” ni ó yọ sí i. Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ni, ńṣe ni a rán an láti wá mú kí Dáníẹ́lì ní ìjìnlẹ̀ òye. (Dáníẹ́lì 8:15-17) Bákan náà, lẹ́yìn àdúrà Dáníẹ́lì, áńgẹ́lì yìí gbé ìrísí ènìyàn wọ̀, ó wá sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ó sì bá a sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń bá ọmọnìkejì rẹ̀ sọ̀rọ̀.

11, 12. (a) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí tẹ́ńpìlì tàbí pẹpẹ Jèhófà ní Bábílónì, báwo ni àwọn Júù tí ó jẹ́ olùfọkànsìn ṣe ń fi hàn pé àwọn bìkítà nípa àwọn ọrẹ ẹbọ tí Òfin béèrè? (b) Èé ṣe tí a fi pe Dáníẹ́lì ní “ẹnì kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi”?

11 “Ìgbà ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn alẹ́” ni Gébúrẹ́lì dé. A ti wó pẹpẹ Jèhófà pọ̀ mọ́ tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, òǹdè àwọn ará Bábílónì abọ̀rìṣà sì ni àwọn Júù jẹ́. Nípa báyìí, àwọn Júù tí ó wà ní Bábílónì kì í rú ẹbọ sí Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n tí ó bá ti tó àwọn àkókò tí Òfin Mósè sọ pé kí wọ́n rú ẹbọ sí Ọlọ́run, ẹ̀tọ́ àwọn Júù olùfọkànsìn tí ó wà ní Bábílónì ni láti fìyìn fún Jèhófà kí wọ́n sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i. Bí Dáníẹ́lì ti jẹ́ ẹni tí ń fọkàn sin Ọlọ́run gidigidi, a pè é ní “ẹnì kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi.” Inú Jèhófà, “Olùgbọ́ àdúrà,” dùn sí i, ó sì rán Gébúrẹ́lì wá kíákíá láti wá dáhùn àdúrà ìgbàgbọ́ tí Dáníẹ́lì gbà.—Sáàmù 65:2.

12 Kódà nígbà tí gbígbàdúrà sí Jèhófà wu ẹ̀mí Dáníẹ́lì léwu, ó ń bá a lọ láti gbàdúrà sí Ọlọ́run lẹ́ẹ̀mẹ́ta lóòjọ́. (Dáníẹ́lì 6:10, 11) Abájọ tí ó fi jẹ́ ẹni tí ó fa Jèhófà lọ́kàn mọ́ra gidigidi tó bẹ́ẹ̀! Ní àfikún sí àdúrà gbígbà, àṣàrò tí Dáníẹ́lì ń ṣe nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún jẹ́ kí ó mọ ohun tí Jèhófà ń fẹ́. Dáníẹ́lì tẹra mọ́ àdúrà gbígbà, ó sì mọ ọ̀nà títọ́ láti gbà tọ Jèhófà lọ kí àdúrà rẹ̀ lè gbà. Ó tẹnu mọ́ jíjẹ́ tí Ọlọ́run jẹ́ olódodo. (Dáníẹ́lì 9:7, 14, 16) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá Dáníẹ́lì kò rí àṣìṣe kankan ká mọ́ ọn lọ́wọ́, ó mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ lòun lójú Ọlọ́run, kò sì jáfara láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.—Dáníẹ́lì 6:4; Róòmù 3:23.

“ÀÁDỌ́RIN Ọ̀SẸ̀” LÁTI FI PA Ẹ̀ṢẸ̀ RẸ́ KÚRÒ

13, 14. (a) Ìsọfúnni pàtàkì wo ni Gébúrẹ́lì sọ fún Dáníẹ́lì? (b) Báwo ni “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” náà ṣe gùn tó, báwo ni a sì ṣe mọ̀?

13 Ìdáhùn tí Dáníẹ́lì, tí ó kún fún àdúrà rí gbà mà ga o! Kì í wulẹ̀ ṣe pé Jèhófà mú kí ó dá a lójú pé a óò dá àwọn Júù padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ kí ó ní ìjìnlẹ̀ òye nípa ohun kan tí ó tún ṣe pàtàkì gidigidi jù bẹ́ẹ̀ lọ—dídé Mèsáyà tí a ṣèlérí náà. (Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18; Aísáyà 9:6, 7) Gébúrẹ́lì sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ wà tí a ti pinnu sórí àwọn ènìyàn rẹ àti sórí ìlú ńlá mímọ́ rẹ, láti lè mú ìrélànàkọjá kásẹ̀ nílẹ̀, àti láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́ kúrò, àti láti ṣe ètùtù nítorí ìṣìnà, àti láti mú òdodo wá fún àkókò tí ó lọ kánrin, àti láti fi èdìdì tẹ ìran àti wòlíì, àti láti fòróró yan Ibi Mímọ́ Nínú Àwọn Ibi Mímọ́. Kí o mọ̀, kí o sì ní ìjìnlẹ̀ òye pé láti ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́ títí di ìgbà Mèsáyà Aṣáájú, ọ̀sẹ̀ méje yóò wà, àti ọ̀sẹ̀ méjì-lé-lọ́gọ́ta. Òun yóò padà, a ó sì tún un kọ́ ní ti gidi, pẹ̀lú ojúde ìlú àti yàrà ńlá, ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà kíkangógó.”—Dáníẹ́lì 9:24, 25.

14 Ìròyìn rere gbáà lèyí o! Ọ̀ràn pé a óò tún Jerúsálẹ́mù kọ́ tí a óò sì mú ìjọsìn ṣíṣe padà bọ̀ sípò nínú tẹ́ńpìlì tuntun nìkan kọ́, “Mèsáyà Aṣáájú” yóò tún fara hàn ní àkókò pàtó kan. Láàárín “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” lèyí yóò ti ṣẹlẹ̀. Níwọ̀n bí Gébúrẹ́lì kò ti mẹ́nu kan ọjọ́, ìwọ̀nyí kì í ṣe ọ̀sẹ̀ ọlọ́jọ́ méje ní gígùn, tí yóò pa pọ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọjọ́ ó dín mẹ́wàá [490]—ọdún kan àti oṣù mẹ́rin péré. Àtúnkọ́ Jerúsálẹ́mù tòun ti “ojúde ìlú àti yàrà ńlá” rẹ̀ tí a sọ tẹ́lẹ̀ gba àkókò tí ó gùn jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀sẹ̀ wọ̀nyẹn jẹ́ ọ̀sẹ̀ ti àwọn ọdún. Mélòó kan nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì òde òní ti dábàá pé ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọdún méje ní gígùn. Bí àpẹẹrẹ, “àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ọdún” ni ìtumọ̀ tí ó wà ní àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé Dáníẹ́lì 9:24 nínú Bíbélì Tanakh—The Holy Scriptures, tí ilé ìtẹ̀wé The Jewish Publication Society tẹ̀ jáde. Bíbélì An American Translation kà pé: “Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ọdún ni a yàn kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ àti ìlú mímọ́ rẹ.” Ìtumọ̀ tí ó jọ èyí fara hàn nínú ẹ̀dà ìtumọ̀ ti Moffatt àti Rotherham.

15. Sáà àkókò mẹ́ta wo ni a pín “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” náà sí, ìgbà wo ni wọn yóò sì bẹ̀rẹ̀?

15 Níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ áńgẹ́lì náà, a óò pín “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” náà sí sáà mẹ́ta: (1) “ọ̀sẹ̀ méje,” (2) “ọ̀sẹ̀ méjì-lé-lọ́gọ́ta,” àti (3) ọ̀sẹ̀ kan. Ìyẹn yóò jẹ́ ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta, [49] òjìlé-nírínwó ọdún ó dín mẹ́fà, [434] àti ọdún méje [7]—tí ó pa pọ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ó dín mẹ́wàá [490]. Ó gbàfiyèsí pé Bíbélì The Revised English Bible kà pé: “Àádọ́rin ọdún ní ìlọ́po méje ni a là kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ àti ìlú mímọ́ rẹ.” Lẹ́yìn ìgbà ìgbèkùn àti ìjìyà àwọn Júù ní Bábílónì fún àádọ́rin ọdún, Ọlọ́run yóò fi ojú rere àkànṣe hàn sí wọn fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ó dín mẹ́wàá tàbí àádọ́rin ọdún ní ìlọ́po méje. Ìbẹ̀rẹ̀ kíkà rẹ̀ jẹ́ láti ìgbà “ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́.” Ìgbà wo ni èyí yóò jẹ́?

“ÀÁDỌ́RIN Ọ̀SẸ̀” NÁÀ BẸ̀RẸ̀

16. Bí àṣẹ Kírúsì ṣe fi hàn, ète wo ni ó fi mú àwọn Júù padà bọ̀ sí ìlú ìbílẹ̀ wọn?

16 Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì mẹ́ta ni ó yẹ kí a gbé yẹ̀ wò ní ti ìbẹ̀rẹ̀ “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” náà. Ti àkọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí Kírúsì pa àṣẹ tí ó sọ pé kí àwọn Júù padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ó kà pé: “Èyí ni ohun tí Kírúsì ọba Páṣíà wí, ‘Gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé ni Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run ti fi fún mi, òun fúnra rẹ̀ sì ti fàṣẹ yàn mí pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù, tí ó wà ní Júdà. Ẹnì yòówù tí ń bẹ láàárín yín nínú gbogbo ènìyàn rẹ̀, kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. Nítorí náà, kí ó gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, tí ó wà ní Júdà, kí ó sì tún ilé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì kọ́—òun ni Ọlọ́run tòótọ́—èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù. Ní ti ẹnikẹ́ni tí ó ṣẹ́ kù ní gbogbo ibi tí ó ti ń ṣe àtìpó, kí àwọn ènìyàn ibi tí ó ń gbé fi fàdákà àti wúrà àti àwọn ẹrù àti àwọn ẹran agbéléjẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe ṣèrànwọ́ fún un fún ilé Ọlọ́run tòótọ́, èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù.’” (Ẹ́sírà 1:2-4) Dájúdájú, ète àṣẹ yìí ní tààràtà ni pé kí tẹ́ńpìlì—“ilé Jèhófà”—dí èyí tí a tún kọ́ sí ọ̀gangan ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀.

17. Kí ni lẹ́tà tí a fún Ẹ́sírà sọ nípa ìdí tí ó fi rìnrìn àjò wá sí Jerúsálẹ́mù?

17 Ìṣẹ̀lẹ̀ kejì ṣẹlẹ̀ ní ọdún keje ìṣàkóso Atasásítà ọba Páṣíà (Atasásítà Longimanus, ọmọ Sásítà Kìíní). Ní ìgbà yẹn, Ẹ́sírà akọ̀wé rin ìrìn-àjò oṣù mẹ́rin láti Bábílónì lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ó gba lẹ́tà àkànṣe kan dání láti ọ̀dọ̀ ọba, ṣùgbọ́n lẹ́tà yẹn kò fún wọn láṣẹ láti tún Jerúsálẹ́mù kọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ tí a yàn fún Ẹ́sírà ni pé kí ó ‘ṣe ilé Jèhófà lẹ́wà.’ Ìdí nìyẹn tí lẹ́tà náà fi tọ́ka sí wúrà àti fàdákà, àwọn ohun èlò ọlọ́wọ̀, àti ọrẹ àlìkámà, wáìnì, epo, àti iyọ̀ fún ìtìlẹyìn ìjọsìn nínú tẹ́ńpìlì, àti pé kí àwọn tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ má sanwó orí mọ́.—Ẹ́sírà 7:6-27.

18. Ìròyìn wo ni ó kó ìdààmú bá Nehemáyà, báwo sì ni Atasásítà Ọba ṣe gbọ́ nípa rẹ̀?

18 Ìṣẹ̀lẹ̀ kẹta ṣẹlẹ̀ ní ọdún mẹ́tàlá lẹ́yìn náà, ní ogún ọdún ìṣàkóso Atasásítà ọba Páṣíà. Nígbà yẹn, Nehemáyà jẹ́ agbọ́tí rẹ̀ ní “Ṣúṣánì ilé aláruru.” Àwọn àṣẹ́kù tí ó padà bọ̀ láti Bábílónì ti tún Jerúsálẹ́mù kọ́ dé àyè kan. Ṣùgbọ́n nǹkan kò fararọ. Nehemáyà gbọ́ pé ‘ògiri Jerúsálẹ́mù ti wó lulẹ̀, a sì ti fi inà sun àwọn ẹnubodè rẹ̀ pàápàá.’ Èyí kó ìdààmú bá a gidigidi, ọkàn rẹ̀ sì dà rú. Nígbà tí ọba bi Nehemáyà léèrè nípa ohun tí ó bà á nínú jẹ́, ó fèsì pé: “Kí ọba kí ó pẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin! Èé ṣe tí ojú mi kò fi ní dá gùdẹ̀ nígbà tí ìlú ńlá náà, ilé àwọn ibi ìsìnkú àwọn baba ńlá mi pa run di ahoro, tí a sì ti fi iná jẹ àwọn ẹnubodè rẹ̀ pàápàá run?”—Nehemáyà 1:1-3; 2:1-3.

19. (a) Nígbà tí Atasásítà Ọba béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Nehemáyà, kí ni Nehemáyà kọ́kọ́ ṣe? (b) Kí ni Nehemáyà béèrè, báwo ni ó sì ṣe gbà pé Ọlọ́run kópa nínú ọ̀ràn náà?

19 Àkọsílẹ̀ nípa Nehemáyà wá ń bá a lọ pé: “Ẹ̀wẹ̀, ọba wí fún mi pé: ‘Kí ni ohun náà tí ìwọ ń wá?’ Lójú-ẹsẹ̀, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run. Lẹ́yìn ìyẹn, mo wí fún ọba pé: ‘Bí ó bá dára lójú ọba, bí ó bá sì jọ pé ìránṣẹ́ rẹ dára níwájú rẹ, kí o rán mi lọ sí Júdà, sí ìlú ńlá àwọn ibi ìsìnkú àwọn baba ńlá mi, kí n lè tún un kọ́.’” Àbá yìí tẹ́ Atasásítà lọ́rùn, ó sì tún gbé ìgbésẹ̀ lórí ohun tí Nehemáyà tún tọrọ lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Bí ó bá dára lójú ọba, kí a fún mi ní àwọn lẹ́tà sí àwọn gómìnà ní ìkọjá Odò [Yúfírétì], kí wọ́n lè jẹ́ kí n kọjá títí èmi yóò fi dé Júdà; pẹ̀lúpẹ̀lù, lẹ́tà kan sí Ásáfù olùṣọ́ ọgbà ọba, kí ó lè fún mi ní igi láti fi ẹ̀là gẹdú kọ́ àwọn ẹnubodè Ilé Aláruru tí ó jẹ́ ti ilé náà, àti fún ògiri ìlú ńlá náà àti fún ilé tí èmi yóò wọ̀.” Nehemáyà gbà pé Jèhófà kópa nínú ọ̀ràn yìí, ó wí pé: “Nítorí náà, ọba fi [àwọn lẹ́tà náà] fún mi, gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ rere Ọlọ́run mi lára mi.”—Nehemáyà 2:4-8.

20. (a) Ìgbà wo ni “ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́” bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́? (b) Ìgbà wo ni “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” náà bẹ̀rẹ̀, ìgbà wo ni ó sì parí? (d) Ẹ̀rí wo ni ó fi hàn pé àwọn déètì ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” náà péye?

20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé oṣù Nísàn, ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ogún ọdún ìṣàkóso Atasásítà ni a fún wọn ní ìyọ̀ǹda, ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn náà ni “ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́” ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́. Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí Nehemáyà dé Jerúsálẹ́mù tí ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìmúpadàbọ̀sípò. Ìrìn àjò Ẹ́sírà gba oṣù mẹ́rin, bẹ́ẹ̀ ni Ṣúṣánì tún jìnnà sí Jerúsálẹ́mù ju ìyẹn lọ, nítorí ó ju ọ̀rìndín-nírínwó-lé-méjì [322] kìlómítà sí ìhà ìlà-oòrùn Bábílónì. A jẹ́ pé àfàìmọ̀ ni kó fi ní jẹ́ apá ìparí ogún ọdún ìṣàkóso Atasásítà, ìyẹn ọdún 455 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Nehemáyà dé Jerúsálẹ́mù. Ìgbà yẹn ni “àádọ́rin ọ̀sẹ̀,” tàbí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ó dín mẹ́wàá tí a sọ tẹ́lẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀. Ó wá parí ní apá ìparí ọdún 36 Sànmánì Tiwa.—Wo “Ìgbà Wo Ni Ìṣàkóso Atasásítà Bẹ̀rẹ̀?” ní ojú ewé kẹtàdín-nígba.

“MÈSÁYÀ AṢÁÁJÚ” FARA HÀN

21. (a) Kí ni a ó ṣàṣeparí rẹ̀ láàárín “ọ̀sẹ̀ méje” àkọ́kọ́, láìsì ka àwọn ipò wo sí? (b) Ọdún wo ni ó yẹ kí Mèsáyà fara hàn, kí sì ni Ìhìn Rere Lúùkù sọ pé ó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn?

21 Ọdún mélòó ló kọjá lọ kí a tó tún Jerúsálẹ́mù kọ́ ní ti gidi? Ó dára, “àkókò wàhálà kíkangógó” ni a sọ pé wọn yóò parí ìmúbọ̀sípò ìlú náà nítorí àwọn ìṣòro tí ó wà láàárín àwọn Júù fúnra wọn àti àtakò láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Samáríà àti àwọn mìíràn. Ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n parí ìwọ̀n tí ó ṣe pàtàkì nínú iṣẹ́ yẹn ní nǹkan bí ọdún 406 ṣááju Sànmánì Tiwa—láàárín “ọ̀sẹ̀ méje” tàbí ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta náà. (Dáníẹ́lì 9:25) Sáà àkókò ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta tàbí òjìlé-nírínwó ọdún ó dín mẹ́fà, ni yóò tẹ̀ lé e. Lẹ́yìn sáà àkókò yẹn, Mèsáyà tí a ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́ náà yóò fara hàn. Tí a bá bẹ̀rẹ̀ sí ka ọ̀rìnlé-nírínwó ọdún ó lé mẹ́ta [483] (àròpọ̀ mọ́kàndínláàádọ́ta àti òjìlé-nírínwó ó dín mẹ́fà) láti ọdún 455 ṣááju Sànmánì Tiwa, yóò mú wa dé ọdún 29 Sànmánì Tiwa. Kí ní ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn? Lúùkù, òǹkọ̀wé Ìhìn Rere, sọ fún wa pé: “Ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìgbà ìjọba Tìbéríù Késárì, nígbà tí Pọ́ńtíù Pílátù jẹ́ gómìnà Jùdíà, tí Hẹ́rọ́dù sì jẹ́ olùṣàkóso àgbègbè Gálílì, . . . ìpolongo Ọlọ́run tọ Jòhánù ọmọkùnrin Sekaráyà wá nínú aginjù. Nítorí náà, ó wá sí gbogbo ìgbèríko tí ó wà ní àyíká Jọ́dánì, ó ń wàásù ìbatisí gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.” “Àwọn ènìyàn náà ti ń fojú sọ́nà” fún Mèsáyà ní ìgbà yẹn.—Lúùkù 3:1-3, 15.

22. Ìgbà wo ni Jésù di Mèsáyà tí a ṣèlérí náà, ọ̀nà wo ni ó sì gbà dà bẹ́ẹ̀?

22 Jòhánù kọ́ ni Mèsáyà tí a ṣèlérí náà. Ṣùgbọ́n Jòhánù sọ nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níṣojú rẹ̀ nígbà tí Jésù ti Násárétì ṣe batisí ní ìgbà ìkórè ọdún 29 Sànmánì Tiwa, ó ní: “Mo rí tí ẹ̀mí ń sọ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àdàbà láti ọ̀run, ó sì bà lé e. Èmi pàápàá kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Ẹni náà gan-an tí ó rán mi láti batisí nínú omi sọ fún mi pé, ‘Ẹnì yòówù tí o bá rí tí ẹ̀mí ń sọ kalẹ̀ lé, tí ó sì dúró, èyí ni ẹni tí ń fi ẹ̀mí mímọ́ batisí.’ Mo sì ti rí i, mo sì ti jẹ́rìí pé ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.” (Jòhánù 1:32-34) Nígbà tí Jésù ṣe batisí, ó di Ẹni Àmì Òróró—Mèsáyà, tàbí Kristi. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, Áńdérù ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù bá Jésù tí a fàmì òróró yàn pàdé, ó sì wá sọ fún Símónì Pétérù pé: “Àwa ti rí Mèsáyà náà.” (Jòhánù 1:41) Bí “Mèsáyà Aṣáájú” ṣe fara hàn ní àkókò rẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn o—ní òpin ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin náà!

ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ INÚ Ọ̀SẸ̀ TÍ Ó KẸ́YÌN

23. Èé ṣe tí “Mèsáyà Aṣáájú” fi ní láti kú, ìgbà wo ni èyí yóò sì ṣẹlẹ̀?

23 Kí ni a ó ṣe láṣeparí nínú ọ̀sẹ̀ àádọ́rin? Gébúrẹ́lì sọ pé sáà “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” ni a ti pinnu “láti lè mú ìrélànàkọjá kásẹ̀ nílẹ̀, àti láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́ kúrò, àti láti ṣe ètùtù nítorí ìṣìnà, àti láti mú òdodo wá fún àkókò tí ó lọ kánrin, àti láti fi èdìdì tẹ ìran àti wòlíì, àti láti fòróró yan Ibi Mímọ́ Nínú Àwọn Ibi Mímọ́.” Láti lè ṣàṣeparí èyí, “Mèsáyà Aṣáájú” náà ní láti kú. Nígbà wo? Gébúrẹ́lì sọ pé: “Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì-lé-lọ́gọ́ta náà, a óò ké Mèsáyà kúrò, kì yóò sì sí nǹkan kan fún un. . . . Yóò sì mú májẹ̀mú máa ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan; àti ní ìdajì ọ̀sẹ̀ náà yóò mú kí ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn kásẹ̀ nílẹ̀.” (Dáníẹ́lì 9:26a, 27a) Àkókò tí ọ̀ràn dórí kókó ni “ìdajì ọ̀sẹ̀ náà,” ìyẹn ni, ní agbedeméjì ọ̀sẹ̀ ọdún tí ó kẹ́yìn.

24, 25. (a) Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ìgbà wo ni Kristi kú, kí sì ni ikú àti àjíǹde rẹ̀ mú wá sí ìparí? (b) Kí ni ikú Jésù mú kí ó ṣeé ṣe?

24 Iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Jésù Kristi ṣe láàárín àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ ní apá ìparí ọdún 29 Sànmánì Tiwa, ó sì gba ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀, ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 33 Sànmánì Tiwa, a “ké” Kristi “kúrò” nígbà tí ó kú lórí òpó igi oró, ní fífi ìwàláàyè rẹ̀ ṣe ìràpadà fún aráyé. (Aísáyà 53:8; Mátíù 20:28) Ìwúlò fífi ẹran àti àwọn ọrẹ ẹbọ tí Òfin kà sílẹ̀ rúbọ dópin nígbà tí Jésù tí a jí dìde gbé ìtóye ẹbọ ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tọ Ọlọ́run lọ ní ọ̀run. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àlùfáà Júù ṣì ń bá a lọ láti rú ẹbọ títí tí a fi pa tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù run ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gba irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ mọ́. A ti fi ẹbọ tí ó dára jù ú lọ rọ́pò rẹ̀, ọ̀kan tí a kò ní padà tún ṣe mọ́ láé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “[Kristi] rú ẹbọ kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ títí lọ fáàbàdà . . . Nítorí nípa ọrẹ ẹbọ ìrúbọ kan ṣoṣo ni òun fi sọ àwọn tí a ń sọ di mímọ́ di pípé títí lọ fáàbàdà.”—Hébérù 10:12, 14.

25 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ṣì ń bá a lọ láti pọ́n aráyé lójú, fífi tí a fi ikú ké Jésù kúrò àti jíjí tí a jí i dìde sí ìyè ti ọ̀run, mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ. Ó ‘mú ìrélànàkọjá kásẹ̀ nílẹ̀, ó pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́ kúrò, ó ṣe ètùtù nítorí ìṣìnà, ó sì mú òdodo wá.’ Ọlọ́run mú májẹ̀mú Òfin, tí ó kó àwọn Júù síta tí ó sì dá wọn lẹ́bi gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀, kúrò. (Róòmù 5:12, 19, 20; Gálátíà 3:13, 19; Éfésù 2:15; Kólósè 2:13, 14) A lè wá pa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn oníwà àìtọ́ tí ó ronú pìwà dà rẹ́, a sì lè mú ìjìyà tí ó lè tipa bẹ́ẹ̀ jẹyọ kúrò wàyí. Ó wá ṣeé ṣe pé kí àwọn tí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ lè bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ ẹbọ ìpẹ̀tù ti Mèsáyà. Wọ́n lè fojú sọ́nà fún àtigba ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni, ìyẹn ni, “ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Róòmù 3:21-26; 6:22, 23; 1 Jòhánù 2:1, 2.

26. (a) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti mú májẹ̀mú Òfin kúrò, májẹ̀mú wo ni a mú kí ó ‘máa ṣiṣẹ́ fún ọ̀sẹ̀ kan’? (b) Kí ní ṣẹlẹ̀ ní òpin ọ̀sẹ̀ àádọ́rin náà?

26 Bí Jèhófà ṣe mú májẹ̀mú Òfin kúrò nípasẹ̀ ikú Kristi ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa nìyẹn. Ọ̀nà wo ni a wá fi lè sọ pé Mèsáyà “mú májẹ̀mú máa ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan”? Nítorí pé ó mú kí májẹ̀mú Ábúráhámù máa bá iṣẹ́ lọ ni. Títí tí ọ̀sẹ̀ àádọ́rin fi parí, àwọn irú ọmọ Ábúráhámù tí wọ́n jẹ́ Hébérù ni Ọlọ́run nawọ́ àwọn ìbùkún májẹ̀mú yẹn sí. Ṣùgbọ́n ní òpin “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” ọdún náà, ní ọdún 36 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pétérù wàásù fún Kọ̀nílíù, ọkùnrin ará Ítálì kan, tí ó jẹ́ olùfọkànsìn àti agbo ilé rẹ̀, àti àwọn Kèfèrí mìíràn. Láti ọjọ́ náà lọ ni a sì ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere láàárín àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè.—Ìṣe 3:25, 26; 10:1-48; Gálátíà 3:8, 9, 14.

27. “Ibi Mímọ́ Nínú Àwọn Ibi Mímọ́” wo ni a fòróró yàn, báwo sì ni?

27 Àsọtẹ́lẹ̀ náà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé a ó fòróró yan “Ibi Mímọ́ Nínú Àwọn Ibi Mímọ́.” Èyí kò tọ́ka sí fífi òróró yan Ibi Mímọ́ Jù Lọ, tàbí yàrá inú lọ́hùn-ún ní tẹ́ńpìlì ti Jerúsálẹ́mù. Gbólóhùn náà, “Ibi Mímọ́ Nínú Àwọn Ibi Mímọ́” tọ́ka sí ibi ibùjọsìn Ọlọ́run ní ọ̀run. Ibẹ̀ ni Jésù ti gbé ìtóye ẹbọ tí ó fi ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rú, fún Baba rẹ̀. Ẹbọ yẹn ni ó fi òróró yàn, tàbí pé ó ṣe ìyàsọ́tọ̀ ohun ti ọ̀run tí ó jẹ́ ògidì nípa tẹ̀mí, èyí tí a fi Ibi Mímọ́ Jù Lọ inú àgọ́ ìjọsìn àti ti tẹ́ńpìlì lẹ́yìn ìgbà náà ṣàpẹẹrẹ.—Hébérù 9:11, 12.

ÀSỌTẸ́LẸ̀ TÍ ỌLỌ́RUN JẸ́RÌÍ SÍ

28. Kí ni ‘fífi èdìdì tẹ ìran àti wòlíì’ túmọ̀ sí?

28 Àsọtẹ́lẹ̀ tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ nípa Mèsáyà tún mẹ́nu kan ‘fífi èdìdì tẹ ìran àti wòlíì’ pẹ̀lú. Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo ohun tí a sọ tẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà—gbogbo ohun tí ẹbọ rẹ̀, àjíǹde rẹ̀, àti ìfarahàn rẹ̀ ní ọ̀run ṣàṣeparí, àti àwọn ohun mìíràn tí ó ṣẹlẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ àádọ́rin náà—ni a óò fi òǹtẹ̀ lù pé Ọlọ́run fọwọ́ sí i, pé yóò jẹ́ òótọ́, àti pé ó ṣeé gbíyè lé. A óò fi èdìdì di ìran náà, ní fífi í mọ sórí Mèsáyà nìkan. Ara rẹ̀ àti ara iṣẹ́ tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe ni yóò ti ní ìmúṣẹ. Inú ohun tí ó bá jẹ mọ́ Mèsáyà tí a sọ tẹ́lẹ̀ náà nìkan ni a ti lè rí ìtumọ̀ tí ó tọ́ nípa ìran náà. Ohunkóhun mìíràn kò lè ṣí èdìdì ìtumọ̀ rẹ̀.

29. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù tí a tún kọ́, kí sì ni ìdí rẹ̀?

29 Gébúrẹ́lì ti sọ tẹ́lẹ̀ níṣàájú pé a óò tún Jerúsálẹ́mù kọ́. Nísinsìnyí, ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun ìlú tí a tún kọ́ náà àti tẹ́ńpìlì rẹ̀, ó wí pé: “Ìlú ńlá náà àti ibi mímọ́ ni àwọn ènìyàn aṣáájú tí ń bọ̀ yóò run. Òpin rẹ̀ yóò sì jẹ́ nípasẹ̀ ìkún omi. Ogun yóò sì wà títí di ìgbà òpin; ohun tí a ti ṣe ìpinnu lé lórí ni ìsọdahoro. . . . Àti lórí ìyẹ́ apá ohun ìríra ni ẹni tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro yóò wà; títí di ìparun pátápátá, ohun tí a ti ṣe ìpinnu lé lórí yóò máa dà jáde sórí ẹni tí ó wà ní ahoro pẹ̀lú.” (Dáníẹ́lì 9:26b, 27b) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yìn “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” náà ni èyí yóò ṣẹlẹ̀, yóò jẹ́ àbájáde àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú “ọ̀sẹ̀” ìkẹyìn náà, nígbà tí àwọn Júù kọ Kristi tí wọ́n sì mú kí a ṣekú pa á.—Mátíù 23:37, 38.

30. Gẹ́gẹ́ bí àwọn àkọsílẹ̀ ìtàn ṣe fi hàn, báwo ni a ṣe mú àṣẹ Olùpàkókòmọ́ Gíga Jù ṣẹ?

30 Àkọsílẹ̀ ìtàn fi hàn pé ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá tí ó jẹ́ ti Róòmù, lábẹ́ Gómìnà Síríà náà, Sẹ́sítọ́sì Gálọ́sì, yí Jerúsálẹ́mù po. Láìka bí àwọn Júù ṣe jà raburabu sí, agbo ọmọ ogun Róòmù wọ ìlú náà tàwọn ti àsíá tàbí ọ̀págun abọ̀rìṣà wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́ ìdí ògiri tẹ́ńpìlì níhà àríwá. Wíwà tí wọ́n wà níbẹ̀ sọ wọ́n di “ohun ìríra” tí ó lè ṣokùnfà ìsọdahoro pátápátá. (Mátíù 24:15, 16) Ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, àwọn ará Róòmù dé bí “ìkún omi,” lábẹ́ Ọ̀gágun Títù, wọ́n sì sọ ìlú náà àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ di ahoro. Ohunkóhun kò dá wọn dúró nítorí pé a ti pàṣẹ rẹ̀—‘a ti ṣe ìpinnu lé e lórí’—láti ọwọ́ Ọlọ́run. Jèhófà, Olùpàkókòmọ́ Gíga Jù, tún ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ!

KÍ LO LÓYE?

• Nígbà tí àádọ́rin ọdún ìdahoro Jerúsálẹ́mù ń parí lọ, àrọwà wo ni Dáníẹ́lì pa sí Jèhófà?

• Báwo ni “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” náà ṣe gùn tó, ìgbà wo ni ó bẹ̀rẹ̀, ìgbà wo ló sì parí?

• Ìgbà wo ni “Mèsáyà Aṣáájú” fara hàn, àkókò tí ọ̀ràn dórí kókó wo ni a sì “ké e kúrò”?

• Májẹ̀mú wo ni a mú kí ó “máa ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan”?

• Kí ní ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” náà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 197]

Ìgbà Wo Ni Ìṣàkóso Atasásítà Bẹ̀rẹ̀?

ÀWỌN òpìtàn kò fohùnṣọ̀kan ní ti ọdún tí ìṣàkóso Atasásítà ọba Páṣíà bẹ̀rẹ̀. Àwọn kan sọ pé ọdún 465 ṣááju Sànmánì Tiwa ni ó gorí ìtẹ́, nítorí pé, Sásítà baba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso lọ́dún 486 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó sì kú ní ọdún kọkànlélógún ìṣàkóso rẹ̀. Àmọ́, ẹ̀rí wà pé Atasásítà gorí ìtẹ́ ní ọdún 475 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó sì bẹ̀rẹ̀ ọdún àkọ́kọ́ ìṣàkóso rẹ̀ ní ọdún 474 ṣááju Sànmánì Tiwa.

Àwọn ohun fífín àti ohun gbígbẹ́ tí wọ́n wú jáde ní Persepolis, olú ìlú Páṣíà ìgbàanì, fi hàn pé Sásítà àti baba rẹ̀ Dáríúsì Kìíní jùmọ̀ ṣàkóso pa pọ̀. Bí èyí bá gba ọdún mẹ́wàá, tí Sásítà sì dá ṣàkóso fún ọdún mọ́kànlá lẹ́yìn ikú Dáríúsì ní ọdún 486 sááju Sànmánì Tiwa, ọdún kìíní ìṣàkóso Atasásítà yóò wá jẹ́ ọdún 474 ṣááju Sànmánì Tiwa.

Ohun ẹ̀rí kejì so pọ̀ mọ́ Ọ̀gágun Tẹ́mísítókù, ará Áténì, tí ó ṣẹ́gun agbo ọmọ ogun Sásítà ní ọdún 480 ṣááju Sànmánì Tiwa. Nígbà tí ó yá, ọ̀rọ̀ òun àti àwọn ará Gíríìsì kò wọ̀ mọ́, wọ́n sì fẹ̀sùn ìdìtẹ̀ sí ìjọba kàn án. Tẹ́mísítókù bá fẹsẹ̀ fẹ, ó lọ forí pamọ́ sí ààfin Páṣíà, wọ́n sì gbà á tọwọ́ tẹsẹ̀ níbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Túsídáìdì, òpìtàn, ará Gíríìsì náà ṣe wí, èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí Atasásítà “ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí ìtẹ́.” Díódórù Síkúlù, òpìtàn, ará Gíríìsì náà, sọ pé Tẹ́mísítókù kú lọ́dún 471 ṣááju Sànmánì Tiwa. Níwọ̀n bí Tẹ́mísítókù ti béèrè pé kí wọ́n jẹ́ kí òun kọ́ èdè Páṣíà fún ọdún kan kí òun tó lè bà Atasásítà Ọba fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀, ó ní láti jẹ́ pé ọdún 473 ó pẹ́ tán ni ó dé Éṣíà Kékeré. Ìwé Chronicle of Eusebius ti Jerome ti èyí lẹ́yìn. Bí ó ti jẹ́ pé ńṣe ni Atasásítà “ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí ìtẹ́” nígbà tí Tẹ́mísítókù dé Éṣíà lọ́dún 473 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ernst Hengstenberg, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, ará Germany, sọ nínú ìwé rẹ̀ Christology of the Old Testament pé ìṣàkóso Atasásítà bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 474 ṣááju Sànmánì Tiwa gẹ́gẹ́ bí àwọn orísun mìíràn náà ṣe sọ. Ó fi kùn un pé: “Ogún ọdún ìṣàkóso Atasásítà jẹ́ ọdún 455 ṣááju Kristi.”

[Àwòrán]

Àwòrán Tẹ́mísítókù, láti igbáàyà sókè

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 188, 189]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

“ÀÁDỌ́RIN Ọ̀SẸ̀”

Ṣááju Sànmánì Tiwa Sànmánì Tiwa

455 406 29 33 36

“Ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù Mèsáyà A ké Òpin

Jerúsálẹ́mù tí a tún kọ́ fara hàn Mèsáyà “àádọ́rin

padà bọ̀ sípò” kúrò ọ̀sẹ̀”

Ọ̀sẹ̀ méje Ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta Ọ̀sẹ̀ kan

Ọdún Òjìlé-nírínwó Ọdún méje

mọ́kàndínláàádọ́ta ọdún ó dín mẹ́fà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 180]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 193]