A Gbà Á Sílẹ̀ Lẹ́nu Àwọn Kìnnìún!
Orí Kẹjọ
A Gbà Á Sílẹ̀ Lẹ́nu Àwọn Kìnnìún!
1, 2. (a) Báwo ni Dáríúsì ará Mídíà ṣe ṣètò ilẹ̀ ọba rẹ̀ tí ó ti gbòòrò sí i? (b) Ṣàpèjúwe àwọn ojúṣe àti àṣẹ tí àwọn baálẹ̀ ní.
BÁBÍLÓNÌ ti ṣubú! Ọláńlá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbára ayé kan tí ó ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún wá ni a fòpin sí láàárín wákàtí mélòó kan. Sànmánì tuntun kan ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ̀rẹ̀ bọ̀—sànmánì ti àwọn Mídíà òun Páṣíà. Bí Dáríúsì ará Mídíà ṣe gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí arọ́pò Bẹliṣásárì, ó gbájú mọ́ iṣẹ́ bàǹtàbanta ti mímú kí ilẹ̀ ọba rẹ̀ tí ó ti gbòòrò sí i wà létòlétò.
2 Ọ̀kan lára iṣẹ́ àkọ́kọ́ tí Dáríúsì mú ṣe ni pé ó yan ọgọ́fà baálẹ̀. A gbà gbọ́ pé, nígbà mìíràn, inú mọ̀lẹ́bí ọba ni a ti máa ń mú àwọn tí a máa ń yàn sí irú ipò iṣẹ́ yìí. Bí ó ti wù kí ó rí, baálẹ̀ kọ̀ọ̀kan a máa ṣàkóso àgbègbè ńlá tàbí ọ̀kan nínú ìpínlẹ̀ kéékèèké tí a pín ilẹ̀ ọba náà sí. (Dáníẹ́lì 6:1) Lára àwọn ojúṣe rẹ̀ ni kí ó gba owó orí kí ó sì fi owó òde ṣọwọ́ sí ààfin. Baálẹ̀ yìí ní àṣẹ púpọ̀ dé àyè kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, lóòrèkóòrè, àwọn aṣojú ọba lè gbé iṣẹ́ rẹ̀ yẹ̀ wò. Ìtumọ̀ oyè rẹ̀ ni “olùdáàbòbo Ìjọba.” Ojú pé ó jẹ́ ọba lábẹ́ àkóso ìjọba ni a fi máa ń wo baálẹ̀ ní ẹkùn tirẹ̀, agbára ọba aláṣẹ nìkan ni kò kàn ní.
3, 4. Èé ṣe tí Dáríúsì fi fi ojú rere hàn sí Dáníẹ́lì, ipò wo ni ọba sì yàn án sí?
3 Ibo wá ni Dáníẹ́lì yóò rí dúró sí nínú ìṣètò tuntun yìí? Ṣé Dáríúsì ará Mídíà yóò fẹ̀yìn arúgbó wòlíì Júù, tí ọjọ́ orí rẹ̀ ti lé ní àádọ́rùn-ún ọdún yìí tì ni? Àgbẹdọ̀! Láìsí àní-àní, Dáríúsì mọ̀ pé Dáníẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìṣubú Bábílónì lọ́nà tí ó péye, àti pé, irú àwítẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ń béèrè agbára ìfòyemọ̀ tí ó ré kọjá ti ẹ̀dá ènìyàn. Pẹ̀lúpẹ̀lù,
Dáníẹ́lì ní ọ̀pọ̀ ọdún ìrírí ní ti bí a ṣe lè bá onírúurú àwùjọ àwọn òǹdè Bábílónì lò. Ṣe ni Dáríúsì fẹ́ kí àjọṣepọ̀ alálàáfíà wà láàárín òun àti àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ́gun. Nítorí náà, ó dájú pé, ẹni tí ó ní irú ọgbọ́n àti ìrírí tí Dáníẹ́lì ní ni yóò fẹ́ kí ó wà nítòsí ọba. Ipò wo ni yóò wà?4 Yóò yani lẹ́nu gidigidi bí Dáríúsì bá yan Dáníẹ́lì, Júù kan tí a kó nígbèkùn, ṣe baálẹ̀. Àmọ́, sáà fojú inú wo bí gọngọ ṣe sọ nígbà tí Dáríúsì kéde ìpinnú rẹ̀ láti fi Dáníẹ́lì ṣe ọ̀kan lára àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga mẹ́ta tí yóò máa bójú tó àwọn baálẹ̀ náà! Ìyẹn nìkan kọ́, Dáníẹ́lì tún “ń fi ara rẹ̀ hàn yàtọ̀ ṣáá,” tí ó fi jẹ́ pé ọwọ́ rẹ̀ ń mókè láàárín àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Ní tòótọ́, a rí i pé “ẹ̀mí àrà ọ̀tọ̀ kan” wà nínú rẹ̀. Dáríúsì tilẹ̀ ní in lọ́kàn láti fi í ṣe olórí àwọn òjíṣẹ́ ọba.—Dáníẹ́lì 6:2, 3.
5. Báwo ni àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ yòókù ṣe ti ní láti hùwà nípa ipò tí a yan Dáníẹ́lì sí, èé sì ti ṣe?
5 Inú àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga yòókù àti àwọn baálẹ̀ ti ní láti ru ṣùṣù. Họ́wù, ara wọn kò gba èrò náà rárá ni, pé kí Dáníẹ́lì—tí kì í ṣe ará Mídíà tàbí Páṣíà, tí kò sì wá láti ìdílé ọba—wá jẹ́ aláṣẹ lé àwọn lórí! Báwo ni Dáríúsì ṣe lè lọ gbé àjèjì kan sí irú ipò gíga bẹ́ẹ̀, ní gbígbójú fo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tirẹ̀, àní àwọn ìdílé tirẹ̀ pàápàá? Gbígbé nǹkan foniru lọ́nà bẹ́ẹ̀ ní láti dà bí ohun tí kò bọ́ sí i rárá ni. Ní àfikún sí i, ó jọ pé àwọn baálẹ̀ wọ̀nyẹn ka ìwà títọ́ Dáníẹ́lì sí ìdíwọ́ tí kò bára dé lójú ìwà jẹgúdújẹrá àti ìwà ìbàjẹ́ tiwọn. Síbẹ̀, àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ wọ̀nyẹn kò jẹ́ kọnu sí Dáríúsì lórí ọ̀ràn náà. Ó ṣe tán, ṣe ni Dáríúsì ń gbé Dáníẹ́lì gẹ̀gẹ̀.
6. Báwo ni àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ ṣe gbìyànjú láti ba ti Dáníẹ́lì jẹ́, èé sì ti ṣe tí ìsapá yìí fi já sí asán?
6 Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn òjòwú òṣèlú wọ̀nyí lẹ̀dí àpò pọ̀. Dáníẹ́lì 6:4, 5.
Wọ́n gbìyànjú “láti rí ohun àfiṣe-bojúbojú lòdì sí Dáníẹ́lì nípa ìjọba náà.” A ha lè rí ìkù-káàtó nínú bí ó ṣe ń bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ bí? Àbòsí ha wà lọ́wọ́ rẹ̀ bí? Àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ kò rí ìwà àìnáání tàbí ìwà ìbàjẹ́ kankan rárá nínú bí Dáníẹ́lì ṣe ń bójú tó iṣẹ́ rẹ̀. Wọ́n fèrò wérò láàárín ara wọn pé: “A kò lè rí ohun àfiṣe-bojúbojú kankan rárá nínú Dáníẹ́lì yìí, bí kò ṣe pé a bá rí i lòdì sí i nínú òfin Ọlọ́run rẹ̀.” Bí àwọn oníbékebèke wọ̀nyẹn ṣe dìmọ̀lù nìyẹn. Wọ́n rò pé ìyẹn ni yóò rẹ́yìn Dáníẹ́lì pátápátá.—A DÁWỌ́ LÉ ÌDÌMỌ̀LÙ AṢEKÚPANI KAN
7. Àbá wo ni àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ dá fún ọba, ọ̀nà wo sì ni wọ́n gbà gbé e kalẹ̀?
7 Àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ para pọ̀ lọ bá Dáríúsì, wọ́n wọlé wá “bí àgbájọ ènìyàn kan.” Ní èdè Árámáíkì, gbólóhùn tí a lò níhìn-ín ní èrò ti ìró bí ààrá. Ó jọ pé ṣe ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí mú kí ó dà bí pé ọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ kánjúkánjú gidi gan-an ni wọ́n bá wá sọ́dọ̀ Dáríúsì. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti rò ó pé kò ní lè béèrè ìbéèrè kankan lórí ìwéwèé wọn bí wọ́n bá fi ìdánilójú sọ ọ́ tí wọ́n sì mú kí ó dà bí pé ó ń fẹ́ ìgbésẹ̀ kánjúkánjú. Nítorí náà, wọ́n tẹnu bọ̀rọ̀ pé: “Gbogbo àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga nínú ìjọba náà, àwọn aṣíwájú àti baálẹ̀, àwọn olóyè onípò gíga àti àwọn gómìnà, ti gbìmọ̀ pọ̀ láti fìdí ìlànà àgbékalẹ̀ ọba múlẹ̀ àti láti mú kí àṣẹ ìkàléèwọ̀ kan rinlẹ̀, pé ẹnì yòówù tí ó bá ṣe ìtọrọ lọ́wọ́ ọlọ́run tàbí ènìyàn èyíkéyìí láàárín ọgbọ̀n ọjọ́ bí kò ṣe lọ́wọ́ rẹ, ọba, ni kí a sọ sínú ihò kìnnìún.” *—Dáníẹ́lì 6:6, 7.
8. (a) Èé ṣe tí òfin tí a dá lábàá yìí yóò fi wu Dáríúsì? (b) Kí ni ète àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ náà ní ti gidi?
8 Àkọsílẹ̀ inú ìtàn jẹ́rìí sí i pé ó wọ́pọ̀ pé kí a ka àwọn
ọba Mesopotámíà sí ọlọ́run, kí a sì máa jọ́sìn wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ìwéwèé yìí wú Dáríúsì lórí. Ó sì ṣeé ṣe kí ó tún rí ìhà kan tí ó wúlò níbẹ̀. Rántí pé Dáríúsì jẹ́ àjèjì àti ẹni tuntun sí àwọn tí ń gbé ní Bábílónì. Ṣe ni òfin tuntun yìí yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba, yóò sì jẹ́ kí àwọn ògìdìgbó tí ń gbé ní Bábílónì lè jẹ́jẹ̀ẹ́ ìdúróṣinṣin àti ìtìlẹyìn fún ìjọba tuntun yìí. Àmọ́ ṣá, kì í ṣe ire ọba ló jẹ àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ lọ́kàn tí wọ́n fi wéwèé òfin yìí. Èrò ọkàn wọn ní ti gidi ni láti kẹ́dẹ mú Dáníẹ́lì, nítorí wọ́n mọ̀ pé ó jẹ́ àṣà rẹ̀ láti máa gbàdúrà sí Ọlọ́run lẹ́ẹ̀mẹ́ta lóòjọ́ ní ìdojúkọ fèrèsé tí ó wà ní ṣíṣí ní ìyẹ̀wù òrùlé rẹ̀.9. Èé ṣe tí òfin tuntun yìí kò fi ní jẹ́ ìṣòro fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí kì í ṣe Júù?
9 Ìkálọ́wọ́kò tí a gbé karí àdúrà gbígbà yìí yóò ha dá ìṣòro sílẹ̀ fún àwùjọ àwọn ẹlẹ́sìn tí ń gbé ní Bábílónì bí? Ó lè máa rí bẹ́ẹ̀, pàápàá bí ó ti jẹ́ pé ìfòfindè náà kò ju oṣù kan péré lọ. Síwájú sí i, díẹ̀ nínú àwọn tí kì í ṣe Júù ni yóò ka dídarí ìjọsìn wọn sí ènìyàn kan fún àkókò kan sí ṣíṣe ohun tí ó lódì sí ìjọsìn ẹni. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa Bíbélì kan sọ pé: “Jíjọ́sìn ọba kì í ṣe ohun àjèjì rárá lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ abọ̀rìṣà jù lọ; nítorí náà, nígbà tí a ní kí àwọn ará Bábílónì fi ìjúbà tí ó tọ́ sí ọlọ́run kan fún ẹni tí ó ṣẹ́gun wọn—Dáríúsì ará Mídíà—wọ́n gbà bẹ́ẹ̀ láìjanpata. Júù yẹn nìkan ni kò fara mọ́ ṣíṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.”
10. Ojú wo ni àwọn Mídíà àti Páṣíà fi ń wo òfin tí ọba wọn bá gbé jáde?
10 Bí ó ti wù kí ó jẹ́, àwọn tí ó tọ Dáríúsì wá rọ̀ ọ́ pé kí ó “fìdí ìlànà àgbékalẹ̀ náà múlẹ̀,” kí ó sì “fọwọ́ sí ìwé náà, nítorí kí a má bàa yí i padà, gẹ́gẹ́ bí òfin àwọn ará Mídíà àti àwọn ará Páṣíà, èyí tí a kì í wọ́gi lé.” (Dáníẹ́lì 6:8) Ní ìhà Ìlà Oòrùn ìgbàanì, ìfẹ́ inú ọba ní a sábà máa ń kà sí èyí tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹ. Èyí ni ó mú kí èrò náà wà pé ó jẹ́ ẹni tí kò lè ṣàṣìṣe. Kódà, òfin kan tí ó lè mú kí a ṣekú pa àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ni a ní láti mú ṣẹ dandan!
11. Báwo ni òfin Dáríúsì yóò ṣe nípa lórí Dáníẹ́lì?
11 Dáríúsì bá buwọ́ lu òfin yẹn láìronú kan Dáníẹ́lì rárá. (Dáníẹ́lì 6:9) Láìmọ̀, bí ó ṣe fọwọ́ sí ìwé pé kí a pa òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí ó kà sí pàtàkì jù lọ nìyẹn o. Bẹ́ẹ̀ ni, ó dájú gbangba pé Dáníẹ́lì máa fara gbá àṣẹ yìí.
A FIPÁ MÚ DÁRÍÚSÌ ṢÈDÁJỌ́ ÒDÌ
12. (a) Gbàrà tí Dáníẹ́lì mọ̀ nípa òfin tuntun náà kí ló ṣe? (b) Àwọn wo ní ń ṣọ́ Dáníẹ́lì, èé sì ti ṣe?
12 Kò pẹ́ tí Dáníẹ́lì fi mọ̀ nípa òfin tí wọ́n fi de àdúrà gbígbà. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó wọnú ilé rẹ̀, ó sì lọ sí ìyẹ̀wù òrùlé rẹ̀ níbi tí àwọn fèrèsé ti wà ní ṣíṣí sílẹ̀ síhà Jerúsálẹ́mù. * Dáníẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Ọlọ́run níbẹ̀ “gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe déédéé ṣáájú èyí.” Ó ṣeé ṣe kí Dáníẹ́lì rò pé òun nìkan ló wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn tí ó di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun sí i ń ṣọ́ ọ. Lójijì, wọ́n “rọ́ gìrìgìrì wọlé,” kò sí àní-àní pé ó jẹ́ lọ́nà ìháragàgà kan náà tí wọ́n fi rọ́ lọ bá Dáríúsì. Wọ́n ti fi ojú ara wọn rí i wàyí—Dáníẹ́lì “ń ṣe ìtọrọ, tí ó sì ń fi taratara bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere níwájú Ọlọ́run rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 6:10, 11) Ọwọ́ àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ ti tẹ ẹ̀rí tí wọ́n ń wá láti fi fẹ̀sùn kan Dáníẹ́lì níwájú ọba.
13. Ẹ̀sùn wo ni àwọn ọ̀tá Dáníẹ́lì lọ fi sùn níwájú ọba?
13 Àwọn ọ̀tá Dáníẹ́lì fọgbọ́n ẹ̀wẹ́ béèrè lọ́wọ́ Dáríúsì pé: “Àṣẹ ìkàléèwọ̀ kan kò ha wà tí o fọwọ́ sí pé ènìyàn èyíkéyìí tí ó bá ṣe ìtọrọ lọ́dọ̀ ọlọ́run tàbí ènìyàn èyíkéyìí láàárín ọgbọ̀n ọjọ́ bí kò ṣe lọ́dọ̀ rẹ, ọba, ni kí a sọ sínú ihò kìnnìún?” Dáríúsì dáhùn pé: “Ọ̀ràn náà fìdí múlẹ̀ dáadáa gẹ́gẹ́ bí òfin àwọn ará Mídíà àti àwọn ará Dáníẹ́lì 6:12, 13.
Páṣíà, èyí tí a kì í wọ́gi lé.” Wàyí o, kíá ni àwọn aditẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun náà tẹnu bọ̀rọ̀. “Dáníẹ́lì, tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìgbèkùn Júdà, kò fi ọ́ pè rárá, ọba, bẹ́ẹ̀ sì ni àṣẹ ìkàléèwọ̀ tí o fọwọ́ sí, ṣùgbọ́n ìgbà mẹ́ta lójúmọ́ ni ó ń ṣe ìtọrọ.”—14. Kí ni ẹ̀rí fi hàn pé ó jẹ́ ìdí tí àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ fi tọ́ka pé Dáníẹ́lì jẹ́ “ọ̀kan nínú ìgbèkùn Júdà”?
14 Ohun pàtàkì ni, pé àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ tọ́ka sí Dáníẹ́lì gẹ́gẹ́ bí “ọ̀kan nínú ìgbèkùn Júdà.” Ó hàn gbangba pé wọ́n fẹ́ tẹnu mọ́ ọn pé Dáníẹ́lì yìí, tí Dáríúsì lọ gbé sí ipò gíga, wulẹ̀ jẹ́ Júù, ẹrú kan lásánlàsàn. Wọ́n gbà gbọ́ pé, nítorí bẹ́ẹ̀, ó ní láti pa òfin mọ́ dandan ni—ohun yòówù kí ọba fi í pè!
15. (a) Báwo ni Dáríúsì ṣe hùwà nípa ìròyìn tí àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ mú wá bá a? (b) Báwo ni àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ ṣe fi ẹ̀tanú wọn sí Dáníẹ́lì hàn síwájú sí i?
15 Bóyá àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ retí pé kí ọba san èrè fún wọn lórí iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ọlọ́gbọ́n féfé tí wọ́n ṣe. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ìyàlẹ́nu ń bẹ níwájú fún wọn. Ìdààmú ńláǹlà bá Dáríúsì lórí ìròyìn tí wọ́n mú wá bá a yìí. Kàkà kí ìbínú Dáríúsì ru sí Dáníẹ́lì tàbí kí ó sọ ọ́ sínú ihò kìnnìún lọ́gán, ṣe ni ó sapá ṣúlẹ̀ gbogbo ọjọ́ náà láti gbà á sílẹ̀. Ṣùgbọ́n òfo ni gbogbo ìsapá rẹ̀ já sí. Láìpẹ́, àwọn onítẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun náà padà wá, nínú ìwà àìnítìjú wọn, wọ́n ní dandan ni kí àwọn ta ẹ̀jẹ̀ Dáníẹ́lì sílẹ̀.—Dáníẹ́lì 6:14, 15.
16. (a) Èé ṣe tí Dáríúsì fi bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Dáníẹ́lì? (b) Ìrètí wo ni Dáríúsì ní nípa Dáníẹ́lì?
16 Dáríúsì rò ó pé kò sí ohun tí òun tún lè ṣe mọ́ lórí ọ̀ràn náà. Òfin ọ̀hún kò ṣeé wọ́gi lé, bẹ́ẹ̀ ni “ẹ̀ṣẹ̀” Dáníẹ́lì kò sì láforíjì. Kìkì ohun tí Dáríúsì lè sọ fún Dáníẹ́lì ni pé “Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn láìyẹsẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò gbà ọ́ sílẹ̀.” Ó dà bí pé Dáríúsì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Dáníẹ́lì. Jèhófà ni ó fún Dáníẹ́lì ní agbára tí ó fi lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìṣubú * Lẹ́yìn náà, wọ́n “gbé òkúta kan wá, wọ́n sì yí i dí ẹnu ihò náà, ọba sì fi èdìdì òrùka àmì-àṣẹ rẹ̀ àti ti òrùka àmì-àṣẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn sé e, kí a má bàa yí nǹkan kan padà nínú ọ̀ràn Dáníẹ́lì.”—Dáníẹ́lì 6:16, 17.
Bábílónì. Ọlọ́run sì tún fún Dáníẹ́lì ní “ẹ̀mí àrà ọ̀tọ̀ kan” tí ó mú kí ó tayọ àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga yòókù. Bóyá Dáríúsì mọ̀ nípa pé Ọlọ́run yìí kan náà ni ó yọ àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta nínú ìléru oníná ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Bóyá ìrètí ọba ni pé kí Jèhófà gba Dáníẹ́lì wàyí, níwọ̀n bí òun Dáríúsì kò ti lè yí òfin tí òun ti buwọ́ lù padà. Nítorí náà, a sọ Dáníẹ́lì sínú ihò kìnnìún.Ọ̀RÀN YÍ PADÀ BÌRÍ
17, 18. (a) Kí ní fi hàn pé ìdààmú bá Dáríúsì lórí ọ̀ràn Dáníẹ́lì? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọba padà lọ síbi ihò kìnnìún láàárọ̀ ọjọ́ kejì?
17 Dáríúsì wá fi ìbànújẹ́ padà sí ààfin rẹ̀. Kò sí olórin kankan tí a mú wá síwájú rẹ̀, nítorí ọkàn rẹ̀ kò fà sí eré ìnàjú. Kàkà bẹ́ẹ̀, Dáríúsì kò sùn mọ́jú, ààwẹ̀ ló fi gbà. “Oorun rẹ̀ gan-an . . . dá lójú rẹ̀.” Ní kùtùkùtù hàì, Dáríúsì lọ síbi ihò kìnnìún náà kánkán. Ó fi ohùn ìbànújẹ́ ké jáde pé: “Dáníẹ́lì, ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè, Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn láìyẹsẹ̀ ha lè gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn kìnnìún bí?” (Dáníẹ́lì 6:18-20) Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún un—àti ìtura ńláǹlà—pé èsì mà ti ibẹ̀ wá o!
18 “Kí ọba kí ó pẹ́ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Ní lílò tí Dáníẹ́lì lo ìkíni ọlọ́wọ̀ yìí, ó ń fi hàn pé òun kò ní ìkùnsínú kankan sí ọba. Ó mọ̀ pé Dáríúsì kọ́ ní ń ṣe inúnibíni sí òun ní ti gidi bí kò ṣe àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ onílara. (Fi wé Mátíù 5:44; Ìṣe 7:60.) Dáníẹ́lì ń bá a lọ pé: “Ọlọ́run mi rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí ẹnu àwọn kìnnìún náà, wọn kò sì run mí, níwọ̀n bí a ti rí mi ní ọlọ́wọ́ mímọ́ níwájú rẹ̀; àti níwájú rẹ pẹ̀lú, ọba, èmi kò gbé ìgbésẹ̀ aṣenilọ́ṣẹ́ kankan.”—Dáníẹ́lì 6:21, 22.
19. Báwo ni àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ ṣe tan Dáríúsì jẹ tí wọ́n sì fẹ̀tàn mú un ṣe ohun tí wọ́n fẹ́?
19 Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣe máa gún Dáríúsì lẹ́rìí-ọkàn tó! Ó mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pé Dáníẹ́lì kò ṣe ohunkóhun tí ó fi yẹ kí a sọ ọ́ sí ihò kìnnìún. Dáríúsì mọ̀ dáadáa pé ṣe ni àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun láti mú kí a pa Dáníẹ́lì, àti pé wọ́n kàn fi ọgbọ́n àrékérekè lo ọba láti ṣàṣeyọrí ète onímọtara-ẹni-nìkan wọn ni. Bí wọ́n ṣe rin kinkin mọ́ ọn pé “gbogbo àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga nínú ìjọba náà” ti fọwọ́ sí i pé kí wọ́n gbé òfin náà kalẹ̀, ṣe ni wọ́n ń dọ́gbọ́n sọ pé àwọn ti fọ̀rọ̀ náà lọ Dáníẹ́lì pẹ̀lú. Dáríúsì yóò fojú àwọn oníbékebèke wọ̀nyí rí èèmọ̀ láìpẹ́. Àmọ́, lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó pàṣẹ pé kí wọ́n yọ Dáníẹ́lì jáde nínú ihò kìnnìún náà. Ìyanu ṣẹlẹ̀, ohunkóhun kò tilẹ̀ ha Dáníẹ́lì lára rárá!—Dáníẹ́lì 6:23.
20. Kí ni ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọ̀tá Dáníẹ́lì tí wọ́n ṣe kèéta rẹ̀?
20 Nísinsìnyí tí Dáníẹ́lì ti bọ́ nínú ewu, ọ̀ràn mìíràn ń bẹ nílẹ̀ fún Dáríúsì láti bójú tó. “Ọba . . . pàṣẹ, wọ́n sì mú àwọn abarapá ọkùnrin tí ó fẹ̀sùn kan Dáníẹ́lì wá, wọ́n sì sọ wọ́n sínú ihò kìnnìún, àwọn ọmọ wọn àti àwọn aya wọn; wọn kò sì tíì dé ìsàlẹ̀ ihò náà kí àwọn kìnnìún náà tó kápá wọn, gbogbo egungun wọn ni wọ́n sì fọ́ túútúú.” *—Dáníẹ́lì 6:24.
21. Ní ti ọ̀nà ìgbàhùwà sí àwọn mẹ́ńbà ìdílé àwọn tí ó bá ṣe ohun tí kò tọ́, ìyàtọ̀ wo ni ó wà nínú Òfin Mósè àti òfin àwọn àwùjọ kan nígbàanì?
21 Pípa tí a pa àwọn onítẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun náà tayatọmọ, láìpa kìkì àwọn nìkan, lè dà bí èyí tí ó ti le koko jù. Ní ìyàtọ̀ sí èyí, Òfin tí Ọlọ́run pèsè nípasẹ̀ wòlíì Mósè sọ Diutarónómì 24:16) Àmọ́ ṣá, nínú àwọn àwùjọ kan nígbàanì, bí ẹnì kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wúwo, kì í ṣe ohun tí ó ṣàjèjì pé kí a pa àwọn mẹ́ńbà ìdílé ẹni tí ó ṣàìtọ́ náà pa pọ̀ mọ́ ọn. Bóyá kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé yẹn má bàa gbẹ̀san lọ́jọ́ iwájú ni a ṣe ń ṣe èyí. Àmọ́, Dáníẹ́lì kọ́ ló fa ohun tí a ṣe sí ìdílé àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ wọ̀nyẹn. Ó ṣeé ṣe kí àjálù tí àwọn ẹni burúkú wọ̀nyẹn fà bá ìdílé wọn tilẹ̀ bà á nínú jẹ́.
pé: “Kí a má ṣe fi ikú pa àwọn baba ní tìtorí àwọn ọmọ, kí a má sì fi ikú pa àwọn ọmọ ní tìtorí àwọn baba. Kí a fi ikú pa olúkúlùkù nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀.” (22. Ìpolongo tuntun wo ni Dáríúsì gbé jáde?
22 Àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ elétekéte ti pòórá. Dáríúsì wá gbé ìpolongo kan jáde pé: “Láti ọ̀dọ̀ mi ni àṣẹ ìtọ́ni kan ti jáde pé, ní gbogbo àgbègbè ìṣàkóso ìjọba mi, kí àwọn ènìyàn máa wárìrì, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run Dáníẹ́lì. Nítorí pé òun ni Ọlọ́run alààyè àti Ẹni tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin, ìjọba rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan tí a kì yóò run, àgbègbè ìṣàkóso rẹ̀ sì wà títí láé. Ó ń gbani sílẹ̀, ó ń dáni nídè, ó sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, nítorí ó ti gba Dáníẹ́lì sílẹ̀ kúrò ní àtẹ́sẹ̀ àwọn kìnnìún.”—Dáníẹ́lì 6:25-27.
SIN ỌLỌ́RUN LÁÌYẸSẸ̀
23. Àpẹẹrẹ wo ni Dáníẹ́lì fi lélẹ̀ ní ti ìṣesí rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba, báwo sì ni a ṣe lè dà bí rẹ̀?
23 Dáníẹ́lì fi àpẹẹrẹ tí ó dára lélẹ̀ fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run òde òní. Ìwà àìlábààwọ́n ló ń hù nígbà gbogbo. Níbi iṣẹ́ ìjọba tí Dáníẹ́lì ń ṣe, ó “jẹ́ ẹni tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, tí kò sì sí ìwà àìnáání tàbí ohun ìsọnidìbàjẹ́ kankan rárá tí a rí nínú rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 6:4) Lọ́nà kan náà, Kristẹni kan ní láti jẹ́ aláápọn lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Èyí kò túmọ̀ sí pé kí ó jẹ́ arẹ́nijẹ lẹ́nu iṣẹ́ ajé, tí ń fi ìwàǹwára lépa ọrọ̀ àlùmọ́nì tàbí ẹni tí ń ṣèpalára fún àwọn ẹlòmíràn láti lè gòkè àgbà lẹ́nu iṣẹ́. (1 Tímótì 6:10) Ìwé Mímọ́ béèrè pé kí Kristẹni fi tọkàntọkàn àti òótọ́ inú ṣe iṣẹ́ rẹ̀ níbi iṣẹ́ “bí ẹni pé fún Jèhófà.”—Kólósè 3:22, 23; Títù 2:7, 8; Hébérù 13:18.
24. Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe fi hàn pé òun kò yẹhùn nínú ọ̀ràn ìjọsìn?
24 Dáníẹ́lì kò yẹhùn rárá lórí ọ̀ràn ìjọsìn rẹ̀. Gbogbo ènìyàn ló mọ̀ pé àṣà rẹ̀ ni láti máa gbàdúrà. Síwájú sí i, àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ mọ̀ dáadáa pé Dáníẹ́lì kò fi ìjọsìn rẹ̀ ṣeré. Ní tòótọ́, wọ́n ní ìdánilójú pé kò ní jáwọ́ nínú ìṣe rẹ̀ yìí bí òfin bá tilẹ̀ kà á léèwọ̀. Àpẹẹrẹ rere lèyí mà jẹ́ fún àwọn Kristẹni òde òní o! A mọ àwọn náà dáadáa pé wọ́n máa ń fi ìjọsìn Ọlọ́run sí ipò kìíní. (Mátíù 6:33) Ó yẹ kí èyí lè hàn kedere sí àwọn tí ń kíyè sí wa, nítorí Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.”—Mátíù 5:16.
25, 26. (a) Kí ni ohun tí àwọn kan yóò sọ nípa ìgbésẹ̀ tí Dáníẹ́lì gbé? (b) Èé ṣe tí Dáníẹ́lì fi kà á sí pé bí òun bá yí ìṣe òun àtẹ̀yìnwá padà, yóò túmọ̀ sí yíyẹhùn?
25 Àwọn kan lè sọ pé Dáníẹ́lì ì bá ti yẹra fún inúnibíni yẹn nípa gbígbàdúrà sí Jèhófà ní ìdákọ́ńkọ́ fún sáà ọgbọ̀n ọjọ́ náà. Ó ṣe tán, kò pọndandan kí ènìyàn wà ní irú ipò kan pàtó kí Ọlọ́run tó gbọ́ àdúrà rẹ̀. Kódà ó mọ àṣàrò inú ọkàn pàápàá. (Sáàmù 19:14) Síbẹ̀síbẹ̀, ojú tí Dáníẹ́lì fi wo àyípadà èyíkéyìí nínú ìṣe rẹ̀ àtẹ̀yìnwá ni pé yóò túmọ̀ sí yíyẹhùn. Èé ṣe?
26 Níwọ̀n bí àwọn ènìyàn ti mọ dáadáa pé ó jẹ́ àṣà Dáníẹ́lì láti máa gbàdúrà, kí ni ohun tí yóò máa fi yé wọn bí ó bá kàn dáwọ́ rẹ̀ dúró wáí? Àwọn tí ó ń rí i ì bá ti kà á sí pé ìbẹ̀rù ènìyàn ti mú Dáníẹ́lì, àti pé àṣẹ ọba ju òfin Jèhófà lọ. (Sáàmù 118:6) Ṣùgbọ́n Dáníẹ́lì fi hàn nípa àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ pé Jèhófà ni òun fún ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe. (Diutarónómì 6:14, 15; Aísáyà 42:8) Àmọ́ ṣá, ní ṣíṣe èyí, Dáníẹ́lì kò fi àìbọ̀wọ̀fúnni dágunlá sí òfin ọba. Síbẹ̀, kò gbọ̀n jìnnìjìnnì kí ó sì juwọ́ sílẹ̀. Ṣe ni Dáníẹ́lì kàn wulẹ̀ ń bá àdúrà gbígbà nínú ìyẹ̀wù òrùlé rẹ̀ lọ, “gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe déédéé” kí àṣẹ ọba tó wáyé.
27. Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí ṣe lè dà bí Dáníẹ́lì nínú (a) wíwà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga? (b) ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn? (d) sísapá láti sáà máa fi ẹ̀mí àlàáfíà gbé pẹ̀lú gbogbo ènìyàn?
27 Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí lè kọ́ ẹ̀kọ́ láti inú àpẹẹrẹ Dáníẹ́lì. Wọ́n jẹ́ ẹni tí ó “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga,” ní ṣíṣe ìgbọràn sí àwọn òfin orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá ń gbé. (Róòmù 13:1) Ṣùgbọ́n, nígbà tí òfin ènìyàn bá forí gbárí pẹ̀lú ti Ọlọ́run, àwọn ènìyàn Jèhófà á mú ìdúró bí ti àwọn àpọ́sítélì Jésù, tí wọ́n fi àìṣojo sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Pé àwọn Kristẹni ṣe èyí kò túmọ̀ sí pé wọ́n ń ṣọ̀tẹ̀ tàbí pé wọ́n gbé ìdìtẹ̀ dìde sí ìjọba. Kàkà bẹ́ẹ̀, ète wọn ni láti sáà máa fi ẹ̀mí àlàáfíà gbé pẹ̀lú gbogbo ènìyàn láti lè “máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́.”—1 Tímótì 2:1, 2; Róòmù 12:18.
28. Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe sin Jèhófà “láìyẹsẹ̀”?
28 Ẹ̀ẹ̀mejì ni Dáríúsì sọ pé Dáníẹ́lì ń sin Ọlọ́run “láìyẹsẹ̀.” (Dáníẹ́lì 6:16, 20) Ní ìpìlẹ̀, ọ̀rọ̀ èdè Árámáíkì tí a tú sí “láìyẹsẹ̀” túmọ̀ sí “rin àrìnyípo.” Ó ń fúnni ní èrò ohun kan tí ń lọ yípo-yípo, tàbí ohun kan tí ó ń bá a lọ kánrin. Bí ìwà títọ́ Dáníẹ́lì ṣe rí nìyẹn. Ọ̀nà ìgbàṣe nǹkan tí kì í yẹ̀ rárá ló ń tọ̀. Kò sí tàbí-tàbí ní ti ohun tí Dáníẹ́lì yóò ṣe bí àwọn àdánwò bá dojú kọ ọ́, yálà kékeré tàbí ńlá. Kò ní yẹ̀ nínú ipa ọ̀nà tí ó ti ń bá bọ̀ láti nǹkan bí ọgọ́rin ọdún sẹ́yìn—ipa ọ̀nà ìdúróṣinṣin àti ìṣòtítọ́ sí Jèhófà.
29. Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní ṣe lè jàǹfààní láti inú ipa ọ̀nà ìṣòtítọ́ tí Dáníẹ́lì tọ̀?
29 Ipa ọ̀nà tí Dáníẹ́lì tọ̀ ni ó yẹ kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run òde òní tọ̀. Ní tòótọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún gbogbo Kristẹni ní ìṣítí pé kí wọ́n gbé àpẹẹrẹ àwọn ẹni ìgbàanì tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yẹ̀ wò. Nípa ìgbàgbọ́, “wọ́n ṣiṣẹ́ òdodo yọrí, wọ́n rí àwọn ìlérí gbà,” àti pé, ní títọ́ka sí Dáníẹ́lì, ó ní wọ́n “dí ẹnu àwọn kìnnìún.” Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà ti òde òní, ẹ jẹ́ kí a fi irú ìgbàgbọ́ àti àìyẹsẹ̀ bí ti Dáníẹ́lì hàn kí a sì “fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.”—[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 7 Ẹ̀rí láti inú àwọn àkọsílẹ̀ ìgbàanì, tí ó fi hàn pé àwọn ọba ìhà Ìlà Oòrùn sábà máa ń sin àwọn ẹranko ẹhànnà bí ohun ọ̀sìn, ṣètìlẹ́yìn fún ọ̀rọ̀ náà pé “ihò kìnnìún” wà ní Bábílónì.
^ ìpínrọ̀ 12 Ìyẹ̀wù òrùlé jẹ́ yàrá àdáni kan tí ẹnì kan lè jókòó sí bí kò bá fẹ́ kí ẹnikẹ́ni yọ òun lẹ́nu.
^ ìpínrọ̀ 16 Ó ṣeé ṣe kí ihò kìnnìún náà jẹ́ àjà ilẹ̀ kan tí a dá lu lókè. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ó tún ní àwọn ìlẹ̀kùn tàbí àgánrándì irin tí a lè gbé sókè kí ẹranko kan lè wọ ibẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 20 A fi ọ̀rọ̀ náà, “fẹ̀sùn kan,” túmọ̀ gbólóhùn èdè Árámáíkì kan tí a tún lè túmọ̀ sí “bani jẹ́.” Èyí gbé ète ibi tí àwọn ọ̀tá Dáníẹ́lì ní yọ.
KÍ LO LÓYE?
• Èé ṣe tí Dáríúsì ará Mídíà fi pinnu láti lo Dáníẹ́lì ní ipò tí ó ga?
• Ìhùmọ̀ oníbékebèke wo ni àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga àti àwọn baálẹ̀ hùmọ̀? Báwo ni Jèhófà ṣe gba Dáníẹ́lì sílẹ̀?
• Ẹ̀kọ́ wo ni o rí kọ́ láti inú kíkíyèsí àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ Dáníẹ́lì?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 114]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 121]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 127]
Dáníẹ́lì sin Jèhófà “láìyẹsẹ̀.” Ìwọ ńkọ́?