Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Dáníẹ́lì—Ìwé tí Ó Dojú kọ Àyẹ̀wò Fínnífínní

Dáníẹ́lì—Ìwé tí Ó Dojú kọ Àyẹ̀wò Fínnífínní

Orí Kejì

Dáníẹ́lì—Ìwé tí Ó Dojú kọ Àyẹ̀wò Fínnífínní

1, 2. Lọ́nà wo ni a gbà fẹ̀sùn kan ìwé Dáníẹ́lì, èé sì ti ṣe tí o fi rò pé ó ṣe pàtàkì láti gbé àwọn ẹ̀rí ìgbèjà rẹ̀ yẹ̀ wó?

FOJÚ inú wò ó pé o wà nínú kóòtù kan, o ń gbọ́ bí ìgbẹ́jọ́ pàtàkì kan ṣe ń lọ lọ́wọ́. A fẹ̀sùn èrú ṣíṣe kan ọkùnrin kan. Agbẹjọ́rò ti ìjọba ń rin kinkin mọ́ ọn pé ọkùnrin náà jẹ̀bi. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, láti ìgbà pípẹ́ ni a ti mọ ẹni tí a fẹ̀sùn kàn náà gẹ́gẹ́ bí oníwàtítọ́ ènìyàn. O kò ha ní fẹ́ láti gbọ́ ẹ̀rí ìgbèjà ti ẹni tí a fẹ̀sùn kàn yẹn bí?

2 Irú ipò tí o wà nìyẹn nígbà tí ó bá di ọ̀ràn ti ìwé Dáníẹ́lì nínú Bíbélì. Gbajúmọ̀ oníwàtítọ́ ènìyàn ni a mọ ẹni tí ó kọ ọ́ sí. Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, ọwọ́ pàtàkì ni a fi mú ìwé tí ń jẹ́ orúkọ rẹ̀. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ìwé náà ti hàn bí ìtàn tòótọ́, tí Dáníẹ́lì kọ, wòlíì Hébérù kan tí ó gbé ayé ní ọ̀rúndún keje sí ìkẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì, tí ó péye, fi hàn pé ìwé rẹ̀ gba sáà nǹkan bí ọdún 618 sí ọdún 536 ṣááju Sànmánì Tiwa, nǹkan bí ọdún tí a mẹ́nu kàn kẹ́yìn yìí sì ni a parí kíkọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n a ti fẹ̀sùn kan ìwé yẹn. Àwọn ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan àti àwọn ìwé atọ́ka mìíràn ń dọ́gbọ́n sọ tàbí kí wọ́n tilẹ̀ kúkú kéde pé ó jẹ́ ayédèrú ìwé.

3. Kí ni ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica wí nípa ìjóòótọ́ ìwé Dáníẹ́lì?

3 Bí àpẹẹrẹ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica gbà pé ìwé Dáníẹ́lì ni a ti fìgbà kan rí “gbà ní gbogbo gbòò pé ó jẹ́ ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ tòótọ́, tí ó ní ojúlówó àsọtẹ́lẹ̀ nínú.” Ìwé Britannica náà wá sọ pé, àmọ́ kásòótọ́, “a kọ” Dáníẹ́lì “lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ní ìgbà tí rògbòdìyàn orílẹ̀-èdè bẹ́ sílẹ̀—nígbà tí àwọn Júù ń jìyà inúnibíni lábẹ́ [ọba Síríà náà] Áńtíókọ́sì Kẹrin Ẹpifánísì.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà sọ pé ọdún tí a kọ ìwé yìí jẹ́ àárín ọdún 167 sí ọdún 164 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ìwé kan náà yìí kéde pé ẹni tí ó kọ ìwé Dáníẹ́lì kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ iwájú bí kò ṣe pé ó wulẹ̀ ṣàgbékalẹ̀ “àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó tojú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ kọjá bí ẹni pé ó jẹ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú.”

4. Ìgbà wo ni ṣíṣe lámèyítọ́ ìwé Dáníẹ́lì bẹ̀rẹ̀, kí ló sì ru irú ìṣelámèyítọ́ bẹ́ẹ̀ sókè ní àwọn ọ̀rúndún àìpẹ́ yìí?

4 Ibo ni irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ ti pilẹ̀? Ṣíṣe lámèyítọ́ ìwé Dáníẹ́lì kì í ṣe nǹkan tuntun. Ọlọ́gbọ́n èrò orí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Porphyry ni ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ní ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa. Bí ti ọ̀pọ̀ ènìyàn nínú Ilẹ̀ Ọba Róòmù, agbára ìdarí tí ẹ̀sìn Kristẹni ní ni kò fi í lọ́kàn balẹ̀. Ó wá kọ ìwé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún láti fi jin ẹ̀sìn “tuntun” yìí lẹ́sẹ̀. Ìkejìlá ni ó fi gbógun ti ìwé Dáníẹ́lì. Porphyry pe ìwé náà ní ayédèrú ìwé tí Júù kan kọ ní ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa. Irú ìgbóguntì bẹ́ẹ̀ wáyé ní ọ̀rúndún kejìdínlógún àti ìkọkàndínlógún. Lójú àwọn olùṣelámèyítọ́ àti àwọn afọgbọ́n-orí-ṣàlàyé ọ̀ràn, kò ṣeé ṣe láti sọ àsọtẹ́lẹ̀—sísọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀. Dáníẹ́lì wá di àyànsọjú jù lọ fún wọn. Lédè mìíràn, àtòun àti ìwé rẹ̀ wá dojú kọ àyẹ̀wò fínnífínní ní kóòtù. Àwọn olùṣelámèyítọ́ sọ pé àwọn ní ọ̀pọ̀ ẹ̀rí lọ́wọ́ láti fi hàn pé kì í ṣe Dáníẹ́lì ni ó kọ ìwé yẹn nígbà ìgbèkùn àwọn Júù ní Bábílónì, bí kò ṣe ẹlòmíràn ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ìgbà náà. * Irú àwọn ìgbóguntì bẹ́ẹ̀ pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí òǹkọ̀wé mìíràn fi kọ ìwé tí ó pè ní Daniel in the Critics’ Den (Dáníẹ́lì Nínú Ihò Àwọn Olùṣelámèyítọ́), láti fi gbèjà rẹ̀.

5. Èé ṣe tí ìbéèrè nípa ìjóòótọ́ ìwé Dáníẹ́lì fi ṣe pàtàkì?

5 Ẹ̀rí ha wà fún ìtìlẹyìn ohun tí àwọn olùṣelámèyítọ́ ń kéde bí? Tàbí òǹkọ̀wé ni ẹ̀rí gbè? Ohun púpọ̀ ni ọ̀ràn yìí kàn. Kì í wulẹ̀ í ṣe iyì ìwé ìgbàanì yìí nìkan ni ọ̀ràn kan, ó kan ọjọ́ iwájú wa pẹ̀lú. Bí ìwé Dáníẹ́lì bá jẹ́ ayédèrú, a jẹ́ pé òfo lásán ni gbogbo ìlérí nípa ọjọ́ ọ̀la aráyé tí ó sọ. Àmọ́ bí àwọn ojúlówó àsọtẹ́lẹ̀ bá wà nínú rẹ̀, láìṣiyèméjì, pẹ̀lú ìháragàgà ni ìwọ yóò fi fẹ́ mọ ohun tí wọn yóò túmọ̀ sí fún wa lónìí. Ní fífi ìyẹn sọ́kàn, jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ohun tí a fi gbógun ti Dáníẹ́lì.

6. Ẹ̀sùn wo ni a sábà máa fi ń kan ìtàn inú Dáníẹ́lì?

6 Bí àpẹẹrẹ, wo ẹ̀sùn tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana fi sùn pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn ìgbàanì [irú bí ìtàn ìkólọ sígbèkùn ní Bábílónì] ni a ti dàrú mọ́ra gan-an” nínú Dáníẹ́lì. Ṣé bẹ́ẹ̀ ni lóòótọ́? Jẹ́ kí a gbé mẹ́ta yẹ̀ wò nínú àwọn ohun tí a pè ní àṣìṣe náà, lọ́kọ̀ọ̀kan.

Ọ̀RÀN ỌBA TÍ A KÒ MẸ́NU KÀN

7. (a) Èé ṣe tí títọ́ka tí Dáníẹ́lì tọ́ka sí Bẹliṣásárì fi jẹ́ ìdùnnú àwọn olùṣelámèyítọ́ Bíbélì láti ìgbà pípẹ́ wá? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí èrò náà pé Bẹliṣásárì jẹ́ ẹni tí a dédé hùmọ̀ sínú ìtàn?

7 Dáníẹ́lì kọ̀wé pé Bẹliṣásárì, “ọmọkùnrin” Nebukadinésárì, ní ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba ní Bábílónì nígbà tí a ṣẹ́gun ìlú ńlá náà. (Dáníẹ́lì 5:1, 11, 18, 22, 30) Láti ìgbà pípẹ́ wá ni àwọn olùṣelámèyítọ́ ti ń ta ko gbólóhùn yìí léraléra, nítorí pé kò sí ibòmíràn tí a tún ti rí orúkọ Bẹliṣásárì yàtọ̀ sí inú Bíbélì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Nábónídọ́sì, arọ́pò Nebukadinésárì, ni àwọn òpìtàn àtijọ́ sọ pé ó jọba kẹ́yìn nínú àwọn ọba Bábílónì. Nípa báyìí, ní ọdún 1850, Ferdinand Hitzig sọ pé ó dájú pé ṣe ni òǹkọ̀wé náà kàn fúnra rẹ̀ hùmọ̀ Bẹliṣásárì kan. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ èrò tí Hitzig sọ yìí kò ha dà bí ti oníwàǹwára kan lójú tìrẹ? Ó ṣe tán, àìkò mẹ́nu kan ọba yìí—pàápàá ní àsìkò kan tí a gbà pé àkọsílẹ̀ ìtàn ṣọ̀wọ́n gidigidi—ha jẹ́ ẹ̀rí pé ní tòótọ́ ni kò fìgbà kan wà rí bí? Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọdún 1854, a wú àwọn ọ̀pá alámọ̀ rìbìtì kan láti inú àwókù Úrì, ìlú ńlá ìgbàanì kan ní Bábílónì, tí ó wà ní ibi tí a ń pè ní gúúsù ilẹ̀ Iraq báyìí. Lára àwọn àkọsílẹ̀ tí Nábónídọ́sì Ọba fín sára amọ̀ wọ̀nyí ni àdúrà kan wà tí ó kọ pé fún “Bel-sar-ussur, ọmọkùnrin mi àgbà.” Kódà àwọn olùṣelámèyítọ́ wọ̀nyí gbà ni dandan, pé: Bẹliṣásárì inú ìwé Dáníẹ́lì lèyí.

8. Báwo ni a ṣe fi hàn pé òtítọ́ ni àpèjúwe Dáníẹ́lì nípa Bẹliṣásárì pé ó jẹ́ ọba tí ń ṣàkóso?

8 Síbẹ̀, kò tíì tẹ́ àwọn olùṣelámèyítọ́ lọ́rùn. Ọ̀kan nínú wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ H. F. Talbot sọ pé: “Èyí kò fẹ̀rí ohunkóhun múlẹ̀.” Ó ní, ọmọkùnrin tí àkọsílẹ̀ yìí sọ lè jẹ́ ọmọdé lásán, bẹ́ẹ̀, ọba tí ń ṣàkóso ni Dáníẹ́lì pè é. Ṣùgbọ́n ní ọdún kan péré lẹ́yìn tí a tẹ àkíyèsí Talbot jáde, a tún wú ọ̀pọ̀ wàláà tí a fín ọ̀rọ̀ sí jáde, tí ó tọ́ka Bẹliṣásárì pé ó ní àwọn akọ̀wé àti àwùjọ òṣìṣẹ́ agboolé. Èyí kò jẹ́ jẹ́ ọmọdé! Níkẹyìn, àwọn wàláà mìíràn dé ọ̀rọ̀ náà ládé nígbà tí wọ́n sọ pé ìgbà kan wà tí Nábónídọ́sì lọ kúrò ní Bábílónì fún ọdún mélòó kan. Àwọn wàláà wọ̀nyí tún fi hàn pé láàárín àkókò yìí, ó “fi ipò ọba” Bábílónì “síkàáwọ́” ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà (Bẹliṣásárì). Nípa bẹ́ẹ̀, ní irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, Bẹliṣásárì ni ọba—ajùmọ̀ṣàkóso pẹ̀lú baba rẹ̀. *

9. (a) Ní èrò wo ni Dáníẹ́lì fi lè sọ pé ọmọ Nebukadinésárì ni Bẹliṣásárì? (b) Èé ṣe tí àwọn olùṣelámèyítọ́ kò tọ̀nà láti ṣàdédé sọ pé Dáníẹ́lì kò tilẹ̀ tani lólobó nípa pé Nábónídọ́sì wà?

9 Bí kò ti tẹ́ àwọn olùṣelámèyítọ́ kan lọ́rùn síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ń ṣàròyé pé Bíbélì kò pe Bẹliṣásárì ní ọmọ Nábónídọ́sì bí kò ṣe ọmọ Nebukadinésárì. Àwọn kan rin kinkin mọ́ ọn pé Dáníẹ́lì kò tilẹ̀ tani lólobó pé ẹnì kan wà tí ń jẹ́ Nábónídọ́sì rárá. Àmọ́, lójú àyẹ̀wò, ṣe ni àtakò méjèèjì wọmi. Ó dà bí pé ọmọbìnrin Nebukadinésárì ni aya Nábónídọ́sì. Ìyẹn yóò mú kí Bẹliṣásárì jẹ́ ọmọ ọmọ Nebukadinésárì. Àti èdè Hébérù àti ti Árámáíkì, kò sí èyí tí ó ní ọ̀rọ̀ tí a fi ń pe “baba àgbà” tàbí “ọmọ ọmọ”; “ọmọ lágbájá” lè túmọ̀ sí “ọmọ ọmọ lágbájá” tàbí kódà “àtọmọdọ́mọ lágbájá.” (Fi wé Mátíù 1:1.) Síwájú sí i, bí àkọsílẹ̀ Bíbélì náà ṣe lọ ṣì lè jẹ́ kí a fi Bẹliṣásárì hàn pé ó jẹ́ ọmọ Nábónídọ́sì. Nígbà tí ọ̀rọ̀ abàmì, tí a fọwọ́ kọ sára ògiri kó jìnnìjìnnì bá Bẹliṣásárì, ó fi ìgbékútà fi ipò kẹta nínú ìjọba lọ ẹnikẹ́ni tí ó bá lè sọ ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ náà. (Dáníẹ́lì 5:7) Èé ṣe tí ó fi jẹ́ ipò kẹta ni ó fi lọni láìṣe ìkejì? Ní ti pé ìyẹn ni ó fi lọni túmọ̀ sí pé àwọn kan ti wà ní ipò kìíní àti ìkejì. Ní tòótọ́, àwọn kan wà níbẹ̀—Nábónídọ́sì àti ọmọ rẹ̀ Bẹliṣásárì ni.

10. Èé ṣe tí àkọsílẹ̀ Dáníẹ́lì nípa ìlà ọba ní Bábílónì fi kún rẹ́rẹ́ ju ti àwọn òpìtàn ìgbàanì?

10 Nítorí náà, pé Dáníẹ́lì mẹ́nu kan Bẹliṣásárì kì í ṣe ẹ̀rí pé ó “da” ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ “rú mọ́ra gan-an.” Ní ìdàkejì èyí, kúlẹ̀kúlẹ̀ bí ìlà ọba Bábílónì ṣe rí ni Dáníẹ́lì túbọ̀ jẹ́ kí a rí ní kedere sí i ju ti àwọn òpìtàn ayé ìgbàanì bí Herodotus, Xenophon, àti Berossus—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìtàn Bábílónì ni ó ń kọ. Kí ló jẹ́ kí Dáníẹ́lì lè ṣàkọsílẹ̀ àwọn kókó tí àwọn kò kọ? Nítorí pé Bábílónì níbẹ̀ ni ó wà. Ìwé tirẹ̀ jẹ́ ti ẹni tí ọ̀ràn ṣojú rẹ̀, kì í ṣe ti afàwọ̀rajà kan ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ìgbà náà.

TA NI DÁRÍÚSÌ ARÁ MÍDÍÀ?

11. Gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì ṣe wí, ta ni Dáríúsì ará Mídíà, ṣùgbọ́n kí ni a ti sọ nípa rẹ̀?

11 Dáníẹ́lì ròyìn pé nígbà tí a ṣẹ́gun Bábílónì, ọba kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Dáríúsì ará Mídíà” bẹ̀rẹ̀ sí jọba. (Dáníẹ́lì 5:31) A kò tí ì rí orúkọ ẹnì kankan tí ń jẹ́ Dáríúsì ará Mídíà nínú àkọsílẹ̀ àwọn òpìtàn ti ayé tàbí tí àwọn awalẹ̀pìtàn. Nípa bẹ́ẹ̀, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica kéde pé “ẹni tí a dédé hùmọ̀ sínú ìtàn” ni Dáríúsì yìí jẹ́.

12. (a) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn olùṣelámèyítọ́ Bíbélì ti mọ̀ ju sísọ tí wọ́n sọ ṣàkó pé Dáríúsì ará Mídíà kò wà rí? Kí ló lè jẹ́ pé ó ṣẹlẹ̀ ní ti ẹni tí Dáríúsì ará Mídíà jẹ́, ẹ̀rí wo ni ó sì tọ́ka sí èyí?

12 Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ti túbọ̀ ṣọ́ra gan-an. Ó ṣe tán, àwọn olùṣelámèyítọ́ ti fìgbà kan rí sọ pé Bẹliṣásárì jẹ́ ẹni tí a “dédé hùmọ̀” bákan náà. Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ náà ni ti Dáríúsì ṣe máa mú wọn ní èké. Ní báyìí, àwọn wàláà ti a fín ọ̀rọ̀ sí ti fi hàn pé Kírúsì ará Páṣíà kò bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́ orúkọ oyè náà, “Ọba Bábílónì,” ní gbàrà tí ó ṣẹ́gun Bábílónì. Olùwádìí kan dábàá pé: “Ẹni yòówù kí ó máa jẹ́ orúkọ oyè náà, ‘Ọba Bábílónì,’ ó ń jọba lábẹ́ àkóso Kírúsì ni, Kírúsì fúnra rẹ̀ kọ́.” Ó ha lè jẹ́ pé Dáríúsì ni orúkọ ipò àṣẹ, tàbí oyè, olóyè alágbára kan, ará Mídíà, tí a fi àkóso Bábílónì sì níkàáwọ́? Àwọn kan dábàá pé ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ọkùnrin kan tí ń jẹ́ Gubaru ni Dáríúsì. Kírúsì fi Gubaru jẹ gómìnà Bábílónì, àwọn àkọsílẹ̀ tí kì í ṣe ti ẹ̀sìn sì jẹ́rìí sí i pé agbára púpọ̀ ń bẹ níkàáwọ́ rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣàkóso. Wàláà kan tí a fín ọ̀rọ̀ sí sọ pé ó yan àwọn ajẹ́lẹ̀ sórí Bábílónì. Ó dùn mọ́ni pé, Dáníẹ́lì kọ ọ́ pé Dáríúsì yan ọgọ́fà baálẹ̀ láti ṣàkóso ìjọba Bábílónì.—Dáníẹ́lì 6:1.

13. Ìdí tí ó bọ́gbọ́n mu wo ni ó wà tí a fi dárúkọ Dáríúsì ará Mídíà nínú ìwé Dáníẹ́lì ṣùgbọ́n tí a kò dárúkọ rẹ̀ nínú àwọn àkọsílẹ̀ ti ayé?

13 Bí àkókò ti ń lọ, ẹ̀rí tí ó túbọ̀ ṣe tààràtà nípa ẹni tí ọba yìí jẹ́ gan-an lè hàn sóde. Bí ó ti wù kí ó rí, àìgbọ́-nǹkankan nípa èyí láti ọ̀dọ̀ àwọn awalẹ̀pìtàn kò lè fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìdí fún pípe Dáríúsì ní “ẹni tí a hùmọ̀ sínú ìtàn,” kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti wíwulẹ̀ sọ pé ayédèrú ni ìwé Dáníẹ́lì látòkè délẹ̀. Ó túbọ̀ mọ́gbọ́n dání gan-an kí a wo àkọsílẹ̀ Dáníẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ẹni tí ọ̀ràn ṣojú rẹ̀, tí ó túbọ̀ ní kúlẹ̀kúlẹ̀ nínú ju ti àkọsílẹ̀ àwọn òpìtàn ayé àtijọ́.

ÌṢÀKÓSO JÈHÓÁKÍMÙ

14. Èé ṣe tí kò fi sí ìtakora láàárín Dáníẹ́lì àti Jeremáyà lórí ọ̀ràn iye ọdún tí Jèhóákímù Ọba fi jọba?

14 Dáníẹ́lì 1:1 kà pé: “Ní ọdún kẹta ìgbà àkóso Jèhóákímù ọba Júdà, Nebukadinésárì ọba Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sàga tì í.” Àwọn olùṣelámèyítọ́ ṣe àríwísí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí nítorí pé kò dà bí pé ó fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú Jeremáyà, tí ó sọ pé ọdún kẹrin Jèhóákímù ni ọdún kìíní ti Nebukadinésárì. (Jeremáyà 25:1; 46:2) Ṣé Dáníẹ́lì ń tako Jeremáyà ni? Lójú ìsọfúnni díẹ̀ sí i, kíá ni ọ̀ràn náà yanjú. Nígbà tí Fáráò Nékò kọ́kọ́ fi Jèhóákímù jọba ní ọdún 628 ṣááju Sànmánì Tiwa, dọ̀bọ̀sìyẹsà lásán ni ó jẹ́ fún alákòóso Íjíbítì yẹn. Èyí jẹ́ nǹkan bí ọdún mẹ́ta ṣáájú kí Nebukadinésárì tó rọ́pò baba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Bábílónì ní ọdún 624 ṣááju Sànmánì Tiwa. Kété lẹ́yìn náà, (ní ọdún 620 ṣááju Sànmánì Tiwa), Nebukadinésárì gbógun ti Júdà, ó sì sọ Jèhóákímù di ọba lábẹ́ àkóso Bábílónì. (2 Àwọn Ọba 23:34; 24:1) Lójú Júù kan tí ń gbé ní Bábílónì, “ọdún kẹta” Jèhóákímù yóò jẹ́ ọdún kẹta tí ọba náà ti ń sin Bábílónì. Ojú ìwòye tí Dáníẹ́lì fi kọ̀wé rẹ̀ nìyẹn. Ṣùgbọ́n Jeremáyà kọ tirẹ̀ lójú ìwòye ti àwọn Júù tí ń gbé nínú Jerúsálẹ́mù gan-an. Nípa bẹ́ẹ̀, ó tọ́ka sí ipò ọba Jèhóákímù bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí Fáráò Nékò ti fi í jọba.

15. Èé ṣe tí àtakò tí a ṣe sí ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wà nínú Dáníẹ́lì 1:1 kò fi lẹ́sẹ̀ nílẹ̀?

15 Ní tòótọ́, ohun tí a pè ní àìbáramu yìí kàn tún fi kún ẹ̀rí náà pé Dáníẹ́lì kọ̀wé rẹ̀ ní Bábílónì nígbà tí ó wà láàárín àwọn Júù tí a kó nígbèkùn ni. Ṣùgbọ́n àṣìṣe kan tún wà nínú àríyànjiyàn lòdì sí ìwé Dáníẹ́lì yìí. Rántí pé ó dájú pé ìwé Jeremáyà wà lárọ̀ọ́wọ́tó ẹni tí ó kọ̀wé Dáníẹ́lì, kódà ó tún tọ́ka sí i. (Dáníẹ́lì 9:2) Bí òǹkọ̀wé Dáníẹ́lì bá jẹ́ ògbóǹkangí aṣèrú bí àwọn olùṣelámèyítọ́ ṣe wí, ṣé yóò jẹ́ dáwọ́ lé títako òǹkọ̀wé kan tí a bọ̀wọ̀ fún gidigidi bí Jeremáyà—kí ó sì tún wá lọ jẹ́ ní ẹsẹ àkọ́kọ́ gan-an nínú ìwé rẹ̀? Rárá o!

ÀWỌN KÚLẸ̀KÚLẸ̀ TÍ Ó ṢE KÓKÓ

16, 17. Báwo ni ẹ̀rí àwọn awalẹ̀pìtàn ṣe ti àkọsílẹ̀ Dáníẹ́lì lẹ́yìn nípa (a) bí Nebukadinésárì ṣe gbé èrè ìsìn kalẹ̀ fún gbogbo ènìyàn rẹ̀ láti jọ́sìn? (b) ìṣògo Nebukadinésárì lórí àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé rẹ̀ ní Bábílónì?

16 Ẹ jẹ́ kí a wá yí àfiyèsí wa kúrò lórí àtakò rẹ̀ sí dáadáa rẹ̀. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ mìíràn nínú ìwé Dáníẹ́lì, tí ó fi hàn pé òǹkọ̀wé yẹn gan-an mọ̀ nípa àwọn àkókò tí ó kọ̀wé nípa rẹ̀.

17 Mímọ̀ tí Dáníẹ́lì mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó fara sin nípa Bábílónì ìgbàanì jẹ́ ẹ̀rí alágbára pé àkọsílẹ̀ rẹ̀ jẹ́ òótọ́. Bí àpẹẹrẹ, Dáníẹ́lì 3:1-6 ròyìn pé Nebukadinésárì gbé arabarìbì ère kan kalẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti jọ́sìn. Àwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣàwárí ẹ̀rí mìíràn pé ọba yìí wọ́nà láti mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ túbọ̀ lọ́wọ́ sí àwọn ìṣe onífẹ̀ẹ́-ìlú-ẹni àti tí ẹ̀sìn. Bákan náà, Dáníẹ́lì ṣàkọsílẹ̀ bí Nebukadinésárì ṣe ṣògo lórí iṣẹ́ ìkọ́lé púpọ̀ tí ó dáwọ́ lé. (Dáníẹ́lì 4:30) Àwọn àkókò òde-òní yìí ni àwọn awalẹ̀pìtàn ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ́rìí sí i pé Nebukadinésárì jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n ṣe ní Bábílónì. Ní ti ìṣògo—họ́wù, ọkùnrin yìí mú kí a fi òǹtẹ̀ orúkọ rẹ̀ lu àwọn bíríkì wọn pàápàá! Àwọn olùṣelámèyítọ́ Dáníẹ́lì kò lè ṣàlàyé bí ẹni tí wọ́n sọ pé ó kọ ayédèrú ìwé nígbà ayé àwọn Mákábì (ọdún 167 sí ọdún 163 ṣááju Sànmánì Tiwa) ṣe lè mọ̀ nípa irú àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé bẹ́ẹ̀—ní nǹkan bí ọ̀rúndún mẹ́rin lẹ́yìn tí ó ti ṣẹlẹ̀, tí èyí sì jẹ́ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí àwọn awalẹ̀pìtàn tó mú wọn wá sójútáyé.

18. Báwo ni àkọsílẹ̀ Dáníẹ́lì nípa oríṣi ìjìyà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nígbà ìṣàkóso Bábílónì àti ìṣàkóso Páṣíà ṣe fi hàn pé ó péye?

18 Ìwé Dáníẹ́lì tún ṣí àwọn ìyàtọ̀ pàtàkì tí ó wà láàárín àwọn òfin Bábílónì àti ti Mídíà òun Páṣíà payá. Bí àpẹẹrẹ, lábẹ́ òfin Bábílónì, a ju àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Dáníẹ́lì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sínú iná ìléru nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣègbọràn sí àṣẹ ọba. Ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún lẹ́yìn náà, a ju Dáníẹ́lì sínú ihò Kìnnìún nítorí pé ó kọ̀ láti ṣègbọràn sí òfin Páṣíà tí ó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀. (Dáníẹ́lì 3:6; 6:7-9) Àwọn kan ti gbìyànjú láti kàn ṣá àkọsílẹ̀ nípa iná ìléru tì pé ó jẹ́ ìtàn àròsọ, ṣùgbọ́n àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí àwọn lẹ́tà gidi tí a kọ láti Bábílónì ìgbàanì, tí ó mẹ́nu kan irú ìjìyà bẹ́ẹ̀ ní pàtó. Ṣùgbọ́n lójú àwọn ará Mídíà òun Páṣíà, ohun ọlọ́wọ̀ ni iná jẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n yíjú sí àwọn ọ̀nà ìjẹniníyà rírorò mìíràn. Nítorí náà, kò ṣàjèjì síni pé ihò kìnnìún wáyé.

19. Ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín ètò òfin ti Bábílónì àti ti Mídíà òun Páṣíà wo ni Dáníẹ́lì mú kí ó ṣe kedere?

19 Ìyàtọ̀ mìíràn tún yọjú. Dáníẹ́lì fi hàn pé Nebukadinésárì lè ṣòfin tàbí kí ó yí i padà bó ṣe fẹ́. Dáríúsì kò lè ṣe ohunkóhun láti fi yí “òfin àwọn ará Mídíà àti àwọn ará Páṣíà” padà—àní títí kan àwọn tí òun fúnra rẹ̀ gbé kalẹ̀! (Dáníẹ́lì 2:5, 6, 24, 46-49; 3:10, 11, 29; 6:12-16) Òpìtàn náà, John C. Whitcomb kọ̀wé pé: “Ìtàn ìgbàanì jẹ́rìí sí ìyàtọ̀ yìí láàárín Bábílónì, níbi tí òfin ti wà lábẹ́ ọba, àti Mídíà òun Páṣíà, níbi tí ọba ti wà lábẹ́ òfin.”

20. Kúlẹ̀kúlẹ̀ wo nípa àsè Bẹliṣásárì ni ó fi hàn pé Dáníẹ́lì fúnra rẹ̀ mọ̀ nípa àwọn àṣà Bábílónì?

20 Àkọsílẹ̀ tí ó wúni lórí nípa àsè Bẹliṣásárì, tí a kọ sínú Dáníẹ́lì orí karùn-ún, sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó pọ̀ gan-an ni. Ó jọ pé ìpápánu àti ọtí wáìnì púpọ̀ gan-an ni àsè náà fi bẹ̀rẹ̀, nítorí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni a tọ́ka sí wáìnì. (Dáníẹ́lì 5:1, 2, 4) Ní ti gidi, kìkì wáìnì ni àwòrán fífín nípa irú àwọn àsè bẹ́ẹ̀ fi hàn pé wọ́n ń mu. Nígbà náà, ó ṣe kedere pé wáìnì ṣe pàtàkì gidigidi nínú irú àwọn àjọyọ̀ bẹ́ẹ̀. Dáníẹ́lì tún mẹ́nu kàn án pé àwọn obìnrin wà níbi àsè yìí—àwọn wáhàrì ọba àti àwọn aya rẹ onípò kejì. (Dáníẹ́lì 5:3, 23) Ìwalẹ̀pìtàn ti kúlẹ̀kúlẹ̀ yìí nípa àṣà àwọn ará Bábílónì lẹ́yìn. Ní sáà àwọn Mákábì, ó lòdì sí èrò àwọn Júù àti ti Gíríìkì pé kí àwọn aya wà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin níbi àsè. Bóyá ìdí nìyẹn tí àwọn ẹ̀dà ìwé Dáníẹ́lì tí Greek Septuagint kọ́kọ́ túmọ̀ fi kọ̀ láti mẹ́nu kan àwọn obìnrin wọ̀nyí. * Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àkókò tí àṣà àwọn Hélénì (Gíríìkì) gbòde yìí ni ẹni tí a sọ pé ó hùmọ̀ ìwé Dáníẹ́lì ì bá gbé láyé, bóyá ní sànmánì kan náà yẹn, nígbà tí a mú ìtumọ̀ ti Septuagint jáde!

21. Àlàyé tí ó bọ́gbọ́n mu jù lọ wo ni ó wà nípa bí Dáníẹ́lì ṣe mọ àwọn àkókò àti àṣà nígbà ìgbèkùn Bábílónì ní àmọ̀dunjú?

21 Lójú irú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wọ̀nyí, ó ṣòro láti gbà gbọ́ pé ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Britannica lè ṣàpèjúwe òǹkọ̀wé Dáníẹ́lì pé ìmọ̀ “tí kò kún tó tí kò sì péye” ni ó ní nípa ìgbà ìkónígbèkùn. Báwo ni ẹni tí ó kọ ayédèrú ìwé ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ìgbà náà yóò ṣe lè mọ àṣà àwọn ará Bábílónì àti Páṣíà ìgbàanì dunjú tó bẹ́ẹ̀? Rántí pẹ̀lú, pé ilẹ̀ ọba méjèèjì ti kúrò lójútáyé tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa. Ó dájú pé kò sí àwọn awalẹ̀pìtàn nígbà yẹn lọ́hùn-ún; bẹ́ẹ̀ ni àwọn Júù ìgbà yẹn kì í lépa ìmọ̀ nípa àṣà àti ìtàn ilẹ̀ òkèèrè. Dáníẹ́lì wòlíì, tí ìgbà yẹn àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣàlàyé ṣojú rẹ̀, nìkan ni ó lè kọ ìwé Bíbélì tí ń jẹ́ orúkọ rẹ̀.

ÀWỌN OHUN MÌÍRÀN LẸ́YÌN ÒDE ÌWÉ DÁNÍẸ́LÌ HA FI Í HÀN PÉ A HÙMỌ̀ RẸ̀ NI BÍ?

22. Kí ni àwọn olùṣelámèyítọ́ wí nípa ibi tí a to Dáníẹ́lì sí nínú àwọn ìwé onímìísí ti Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù?

22 Ọ̀kan lára ìjiyàn tí ó wọ́ pọ̀ jù lọ lòdì sí ìwé Dáníẹ́lì dá lórí ibi tí a tò ó sí nínú àwọn ìwé onímìísí ti Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Àwọn olùkọ́ni ìgbàanì to àwọn ìwé inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí ọ̀nà mẹ́ta: Òfin, àwọn Wòlíì, àti àwọn Ìwé. Wọ́n kò to Dáníẹ́lì sí ara àwọn Wòlíì bí kò ṣe sí ara àwọn Ìwé. Àwọn olùṣelámèyítọ́ sọ pé èyí túmọ̀ sí pé ó ní láti jẹ́ pé wọn kò mọ ìwé yẹn nígbà tí a ń kó ìwé àwọn wòlíì yòókù jọ. Wọ́n ní nítorí pé lẹ́yìn ìgbà náà ni a kó àwọn Ìwé jọ ni a ṣe tò ó pẹ̀lú wọn.

23. Ojú wo ni àwọn Júù ìgbàanì fi wo ìwé Dáníẹ́lì, báwo ni a sì ṣe mọ èyí?

23 Àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn olùṣèwádìí lórí Bíbélì ni ó gbà pé ṣe ni àwọn olùkọ́ni ìgbàanì to àwọn ìwé onímìísí lọ́nà kan pàtó tí kò ṣeé yí padà tàbí pé wọ́n yọ Dáníẹ́lì kúrò nínú àwọn Wòlíì. Ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara àwọn Ìwé ni àwọn olùkọ́ni to Dáníẹ́lì sí, èyí yóò ha fi hàn pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà náà ni a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ ọ́ bí? Rárá. Àwọn gbajúmọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ti dábàá àwọn ìdí mélòó kan tí ó lè fà á tí àwọn olùkọ́ni fi yọ Dáníẹ́lì kúrò lára àwọn Wòlíì. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé nítorí pé ìwé náà ń bí wọn nínú tàbí nítorí pé wọ́n ka Dáníẹ́lì alára sí ẹni tí ó yàtọ̀ pátápátá sí àwọn wòlíì yòókù ní ti pé ó jẹ́ ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba ilẹ̀ àjèjì. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun tí ó ṣe pàtàkì ní ti gidi ni pé: Àwọn Júù ìgbàanì bọ̀wọ̀ fún ìwé Dáníẹ́lì gidigidi, wọ́n sì kà á kún ara ìwé onímìísí. Ní àfikún sí i, ẹ̀rí tọ́ka pé tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa ni a ti parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìwé onímìísí ti Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. A kò fàyè gba àwọn àfikún ẹ̀yìn ìgbà náà rárá, títí kan àwọn ìwé kan tí a kọ ní ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa.

24. Báwo ni a ti ṣe lo ìwé ajẹmọ́-àròkọ náà, Ecclesiasticus, láti fi tako ìwé Dáníẹ́lì, kí ní sì fi hàn pé èrò yìí kù káàtó?

24 Kàyéfì ni ó jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn ìwé wọ̀nyí tí a kọ lẹ́yìn náà, tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀, ni a tún lò láti fi tako ìwé Dáníẹ́lì. Ó dájú pé nǹkan bí ọdún 180 ṣááju Sànmánì Tiwa ni a kọ ìwé ajẹmọ́-àròkọ náà, Ecclesiasticus, láti ọwọ́ Jesus Ben Sirach. Àwọn olùṣelámèyítọ́ fẹ́ràn títọ́ka pé ìwé náà kò fi Dáníẹ́lì kún àwọn ẹni olódodo tí ó kọ sínú ìwé rẹ̀. Wọ́n ṣàlàyé pé ó ní láti jẹ́ pé a kò mọ Dáníẹ́lì ní àkókò náà. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ fara mọ́ ìjiyàn yìí gidi gan-an ni. Ṣùgbọ́n ro èyí wò ná: Àkọsílẹ̀ orúkọ yìí kan náà kò fi Ẹ́sírà àti Módékáì (tí àwọn méjèèjì jẹ́ akọni lójú àwọn Júù lẹ́yìn ìgbà ìgbèkùn), Jèhóṣáfátì ọba rere, àti Jóòbù adúróṣánṣán kún wọn; nínú gbogbo àwọn onídàájọ́, Sámúẹ́lì nìkan ni ó dárúkọ. * A ha lè ka gbogbo wọn sí ẹni tí a dédé hùmọ̀ nítorí pé a kò mẹ́nu kan irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ orúkọ kan tí a kò sọ pé ó jẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, tí ó wà nínú ìwé kan tí kì í ṣe onímìísí bí? Èrò yẹn pàápàá kò bọ́gbọ́n mu.

Ẹ̀RÍ ÀTÒDEWÁ TÍ Ó TI ÌWÉ DÁNÍẸ́LÌ LẸ́YÌN

25. (a) Báwo ni Josephus ṣe jẹ́rìí sí ìjóòótọ́ àkọsílẹ̀ Dáníẹ́lì? (b) Ọ̀nà wo ni àkọsílẹ̀ Josephus nípa Alẹkisáńdà Ńlá àti ìwé Dáníẹ́lì gbà wà ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn tí a mọ̀? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé kejì.) (d) Báwo ni ẹ̀rí ti ọ̀ràn èdè ṣe ti ìwé Dáníẹ́lì lẹ́yìn? (Wo ojú ìwé kẹrìndínlọ́gbọ̀n.)

25 Ẹ jẹ́ kí a tún yí àfiyèsí wa síhà tí ó dára. A ti dábàá rẹ̀ pé kò tún sí ìwé inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí a jẹ́rìí sí dáadáa tó ti Dáníẹ́lì. Láti ṣàkàwé rẹ̀: Gbajúmọ̀ òpìtàn àwọn Júù náà, Josephus, jẹ́rìí sí ìjóòótọ́ rẹ̀. Ó sọ pé nígbà tí Alẹkisáńdà Ńlá ń bá ilẹ̀ Páṣíà jagun ní ọ̀rúndún kẹrin ṣááju Sànmánì Tiwa, ó wá sí Jerúsálẹ́mù, níbi tí àwọn àlùfáà ti fi ẹ̀dà ìwé Dáníẹ́lì hàn án. Alẹkisáńdà fúnra rẹ̀ dé òpin èrò náà pé àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì tí a fi han òun ń tọ́ka sí bí òun fúnra òun ṣe gbé ogun ja Páṣíà. * Nǹkan bí ọ̀rúndún kan àti ààbọ̀ sì ni èyí máa jẹ́ sí ìgbà tí àwọn olùṣelámèyítọ́ ń dá lábàá pé a ‘hùmọ̀ ìwé’ náà. Àmọ́ ṣá o, àwọn olùṣelámèyítọ́ gbógun ti Josephus lórí àyọkà yìí. Wọ́n tún gbógun tì í lórí sísọ tí ó sọ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú ìwé Dáníẹ́lì ní ìmúṣẹ. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òpìtàn náà, Joseph D. Wilson, ṣe sọ, “Ó dà bí pé [Josephus] mọ bí ọ̀ràn náà ṣe jẹ́ ju olùṣelámèyítọ́ èyíkéyìí lọ ní ayé.”

26. Báwo ni àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ṣe ti ìjóòótọ́ ìwé Dáníẹ́lì lẹ́yìn?

26 Ìtìlẹyìn síwájú sí i pé ìwé Dáníẹ́lì jẹ́ òótọ́ tún wáyé nígbà tí a ṣàwárí àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ní àwọn hòrò kan ní Qumran, ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Àwọn àkájọ àti àjákù ìwé Dáníẹ́lì pọ̀ lọ́nà tí ó yani lẹ́nu lára àwọn ohun tí a ṣàwárí náà lọ́dún 1952. Èyí tí ọjọ́ orí rẹ̀ pẹ́ jù lọ ní a sọ pé ó jìnnà sẹ́yìn tó ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa. Nítorí náà, nígbà ìjímìjí yẹn lọ́hùn-ún ni ìwé Dáníẹ́lì ti gbajúmọ̀ tí a sì ti bọ̀wọ̀ fún un káàkiri ibi púpọ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Zondervan Pictorial Encyclopedia of the Bible sọ pé: “Ó tó kí a pa sísọ tí a ń sọ pé ìgbà àwọn Mákábì ni a kọ ìwé Dáníẹ́lì tì báyìí, ì báà tilẹ̀ jẹ́ kìkì nítorí pé kò ní lè sí àlàfo àkókò tí ó pọ̀ tó láàárín ìgbà tí a kọ ìwé Dáníẹ́lì àti ìgbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí rí àwọn ẹ̀dà rẹ̀ nínú àwọn ibi ìkówèésí àwọn ẹ̀ya ẹ̀sìn àwọn Mákábì.”

27. Kí ni ẹ̀rí tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ pé ẹni gidi kan tí ó gbajúmọ̀ ni Dáníẹ́lì nígbà ìkólọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì?

27 Ṣùgbọ́n, ẹ̀rí tí ó túbọ̀ lọ́jọ́ lórí tí ó sì túbọ̀ ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé ju wà fún ìwé Dáníẹ́lì. Ọ̀kan lára àwọn alájọgbáyé Dáníẹ́lì ni wòlíì Ìsíkíẹ́lì. Òun pẹ̀lú sìn gẹ́gẹ́ bí wòlíì nígbà ìkólọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ìwé Ìsíkíẹ́lì dárúkọ Dáníẹ́lì gan-an. (Ìsíkíẹ́lì 14:14, 20; 28:3) Àwọn ìtọ́kasí wọ̀nyí fi hàn pé, kódà nígbà ayé tirẹ̀ pàápàá, ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa, Dáníẹ́lì ti lókìkí dáadáa gẹ́gẹ́ bí olódodo àti ọlọ́gbọ́n ènìyàn, tí a fi lè dárúkọ rẹ̀ pa pọ̀ mọ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run bí Nóà àti Jóòbù.

Ẹ̀RÍ TÍ Ó GA JÙ LỌ

28, 29. (a) Kí ni ẹ̀rí ayínilérò-padà jù lọ nípa pé ìwé Dáníẹ́lì jẹ́ òótọ́? (b) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a tẹ́wọ́ gba ẹ̀rí Jésù?

28 Paríparì rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a gbé èyí tí ó ga jù lọ nínú àwọn tí ó jẹ́rìí sí ìjóòótọ́ ìwé Dáníẹ́lì yẹ̀ wò—kì í ṣe ẹni méjì, Jésù Kristi ni. Nígbà ìjíròrò rẹ̀ lórí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, Jésù tọ́ka sí “Dáníẹ́lì wòlíì” àti sí ọ̀kan lára àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì.—Mátíù 24:15; Dáníẹ́lì 11:31; 12:11.

29 Wàyí o, bí àbá èrò orí ti títọ́ka sí ìgbà àwọn Mákábì, tí àwọn olùṣelámèyítọ́ gbé kalẹ̀ bá tọ̀nà, ọ̀kan nínú ohun méjì yóò jẹ́ òtítọ́. Yálà kí ó jẹ́ pé ayédèrú ìwé yìí ti tan Jésù jẹ tàbí kí ó jẹ́ pé kò sọ ohun tí Mátíù sọ pé ó sọ rárá. Kò sí èyí tí ó jánà nínú méjèèjì. Bí àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere Mátíù kò bá ṣeé gbára lé, báwo ni a ṣe lè gbára lé àwọn apá yòókù nínú Bíbélì? Bí a bá yọ àwọn gbólóhùn wọ̀nyẹn kúrò, àwọn ọ̀rọ̀ wo ni yóò tún kàn láti fà tu kúrò lójú ewé Ìwé Mímọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, . . . fún mímú àwọn nǹkan tọ́.” (2 Tímótì 3:16) Nítorí náà, bí Dáníẹ́lì bá jẹ́ aṣèrú, Pọ́ọ̀lù náà mà jẹ́ bẹ́ẹ̀ nìyẹn o! Ó ha lè jẹ́ pé ṣe ni a tan Jésù jẹ bí? Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ó wà láàyè ní ọ̀run nígbà tí a ń kọ ìwé Dáníẹ́lì. Jésù tilẹ̀ sọ pé: “Kí Ábúráhámù tó wà, èmi ti wà.” (Jòhánù 8:58) Nínú gbogbo ènìyàn tí ó tí ì gbé ayé rí, Jésù gan-an ni yóò dára jù lọ kí a bi léèrè nípa ìjóòótọ́ ìwé Dáníẹ́lì. Ṣùgbọ́n kò sí ìdí fún wa láti ṣẹ̀ṣẹ̀ béèrè. Bí a ti ṣe rí i, yékéyéké ní ẹ̀rí rẹ̀ yéni.

30. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́rìí sí ìjóòótọ́ ìwé Dáníẹ́lì síwájú sí i?

30 Jésù tún jẹ́rìí sí ìjóòótọ́ ìwé Dáníẹ́lì nígbà tí ó ṣe batisí gan-an. Ìgbà náà ni ó di Mèsáyà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin ti àwọn ọdún ṣẹ. (Dáníẹ́lì 9:25, 26; wo Orí Kọkànlá ìwé yìí.) Ká tilẹ̀ ní àbá náà pé a kọ̀wé Dáníẹ́lì ní ìgbà pípẹ́ sí ìgbà tí ó sọ jẹ́ òótọ́, òǹkọ̀wé Dáníẹ́lì ṣì mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí igba ọdún ṣáájú. Ó tilẹ̀ dájú pé Ọlọ́run kò ní mí sí aṣèrú kan pé kí ó lo orúkọ awúrúju láti sọ àsọtẹ́lẹ̀. Rárá ó, tọkàntọkàn ni àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ọlọ́run fi tẹ́wọ́ gba ẹ̀rí Jésù yìí. Bí gbogbo àwọn ògbógi onímọ̀, gbogbo àwọn olùṣelámèyítọ́ ayé yìí, bá para pọ̀ ṣọ̀kan láti bẹnu àtẹ́ lu Dáníẹ́lì, ẹ̀rí Jésù yóò já wọn nírọ́, nítorí pé òun ni “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́.”—Ìṣípayá 3:14.

31. Èé ṣe tí èrò ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣelámèyítọ́ Bíbélì kò fi tíì yí padà síbẹ̀síbẹ̀ lórí ìjóòótọ́ ìwé Dáníẹ́lì?

31 Àní ẹ̀rí yìí pàápàá kò tó lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣelámèyítọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn gbígbé kókó yìí yẹ̀ wò fínnífínní, kò ní ṣàì hàn síni pé bóyá ni iyekíye ẹ̀rí yòówù kí a kó jọ lè tó láti yí wọn lérò padà. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní Yunifásítì Oxford kọ̀wé pé: “Kò ṣàǹfààní kankan láti kàn máa dáhùn àwọn àtakò, níwọ̀n bí ẹ̀tanú àkọ́kọ́ náà pé, ‘kò lè sí àsọtẹ́lẹ̀ láti orísun tí ó ga ju ti ẹ̀dá ènìyàn lọ,’ bá ṣì wà.” Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀tanú wọn ni ó fọ́ wọn lójú. Àmọ́ ṣá, ohun tí wọ́n yàn nìyẹn—àdánù tiwọn sì ni.

32. Kí ní ń bẹ níwájú fún wa bí a óò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ Dáníẹ́lì?

32 Ìwọ ńkọ́? Bí o bá ti lè rí i pé kò sí ìdí kan gúnmọ́ láti ṣiyèméjì nípa ìjóòótọ́ ìwé Dáníẹ́lì, a jẹ́ pé o ṣe tán láti bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò ìṣàwárí tí ń mórí ẹni yá gágá nìyẹn. Ìwọ yóò rí i pé ọ̀nà ìgbàsọ̀tàn inú Dáníẹ́lì wúni lórí, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sì wuni. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìwọ yóò rí i pé ṣe ni ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ ń lágbára sí i bí o ṣe ń ka àkòrí kọ̀ọ̀kan. Ìwọ kì yóò kábàámọ̀ láé pé o kíyè sí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì kínníkínní!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 4 Àwọn olùṣelámèyítọ́ kan gbìyànjú láti rọ ẹ̀sùn pé ó jẹ́ ayédèrú lójú nípa sísọ pé ńṣe ni ẹni tí ó kọ ọ́ fi orúkọ Dáníẹ́lì bojú, bí wọ́n ṣe lo àwọn awúrúju orúkọ fún àwọn ìwé ìgbàanì kan tí a kò kà sí ara Ìwé Mímọ́. Àmọ́, olùṣelámèyítọ́ Bíbélì náà, Ferdinand Hitzig, sọ pé: “Ọ̀ràn ti ìwé Dáníẹ́lì yàtọ̀ tí a bá fi lè sọ pé ẹlòmíràn ni [ó kọ ọ́]. A jẹ́ pé ayédèrú ìwé ni, ète rẹ̀ sì ni láti fi tan àwọn tí ó máa kà á nígbàanì jẹ, ṣùgbọ́n fún ire tiwọn ni ṣá.”

^ ìpínrọ̀ 8 Kò sí Nábónídọ́sì nílé nígbà tí Bábílónì ṣubú. Nípa báyìí, lọ́nà ẹ̀tọ́, a júwe Bẹliṣásárì gẹ́gẹ́ bí ọba ní ìgbà náà. Àwọn olùṣelámèyítọ́ ń kùn pé àwọn àkọsílẹ̀ tí kì í ṣe ti ìsìn kò pe ọba mọ́ Bẹliṣásárì gẹ́gẹ́ bí orúkọ oyè rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ẹ̀rí tí ó jẹ́ ti ìgbàanì fi hàn pé àwọn ará ìgbà yẹn tilẹ̀ lè pe gómìnà pàápàá ní ọba.

^ ìpínrọ̀ 20 Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú èdè Hébérù náà, C. F. Keil, kọ̀wé nípa Dáníẹ́lì 5:3 pé: “LXX. (Bíbélì Greek Septuagint) kọ̀ láti mẹ́nu kan àwọn obìnrin níhìn-ín àti ní ẹsẹ ìkẹtàlélógún pẹ̀lú, ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àwọn ará Makedóníà, àwọn Gíríìkì àti ti Róòmù.”

^ ìpínrọ̀ 24 Ní ìyàtọ̀ sí èyí, àkọsílẹ̀ onímìísí ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí ó dárúkọ àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ nínú Hébérù orí ìkọkànlá, dà bí pé ó dọ́gbọ́n tọ́ka sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọ sínú Dáníẹ́lì. (Dáníẹ́lì 6:16-24; Hébérù 11:32, 33) Àmọ́ ṣá, àkọsílẹ̀ orúkọ ti àpọ́sítélì náà kò kún rẹ́rẹ́ bákan náà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀, títí kan Aísáyà, Jeremáyà àti Ìsíkíẹ́lì, ni a kò dárúkọ nínú àkọsílẹ̀ yìí, ṣùgbọ́n ó ṣòro kí èyí tó jẹ́ ẹ̀rí pé ṣe ni wọn kò wà rí rárá.

^ ìpínrọ̀ 25 Àwọn òpìtàn kan ti sọ pé èyí jẹ́ kí a mọ ìdí tí Alẹkisáńdà fi yọ́nú gan-an sí àwọn Júù, tí wọ́n ti fìgbà pípẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn ará Páṣíà. Orí ìgbétásì láti pa gbogbo ọ̀rẹ́ ilẹ̀ Páṣíà run ni Alẹkisáńdà wà ní ìgbà yẹn.

KÍ LO LÓYE?

• Ẹ̀sùn kí ni a fi kan ìwé Dáníẹ́lì?

• Èé ṣe tí àtakò àwọn olùṣelámèyítọ́ ìwé Dáníẹ́lì kò fi lẹ́sẹ̀ nílẹ̀?

• Ẹ̀rí wo ni ó ti ìjóòótọ́ àkọsílẹ̀ Dáníẹ́lì lẹ́yìn?

• Kí ni ẹ̀rí ayínilérò-padà jù lọ pé ìwé Dáníẹ́lì jẹ́ òótọ́?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]

Ọ̀ràn Èdè

NǸKAN bí ọdún 536 ṣááju Sànmánì Tiwa ni kíkọ ìwé Dáníẹ́lì parí. Èdè Hébérù àti ti Árámáíkì ni a fi kọ ọ́, tí àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì àti ti Páṣíà mélòó kan sì wà nínú rẹ̀. Irú àdàpọ̀ èdè bẹ́ẹ̀ kò wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n kò ṣàjèjì nínú Ìwé Mímọ́. Èdè Hébérù àti ti Árámáíkì ni a fi kọ ìwé Ẹ́sírà nínú Bíbélì pẹ̀lú. Síbẹ̀ àwọn olùṣelámèyítọ́ kan rin kinkin mọ́ ọn pé òǹkọ̀wé Dáníẹ́lì lo àwọn èdè wọ̀nyí lọ́nà tí ó fi hàn pé ńṣe ni ó ń kọ̀wé ní ìgbà kan tí ó jẹ́ lẹ́yìn ọdún 536 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ń sọ ọ́ pé olùṣelámèyítọ́ kan sọ pé lílò tí a lo àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì nínú Dáníẹ́lì ń béèrè pé kí ìgbà tí a kọ ọ́ jẹ́ ẹ̀yìn ìgbà tí Gíríìsì gbàkóso. Ó ní èdè Hébérù inú rẹ̀ ti èyí lẹ́yìn, pé ó kéré tán ti Árámáíkì fàyè gba irú àkókò bẹ́ẹ̀—kódà ó fàyè gba pé kí ó jẹ́ láìpẹ́ ní ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa.

Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ lórí èdè ni ó gbà bẹ́ẹ̀. Àwọn ògbógi kan ti sọ pé èdè Hébérù tí Dáníẹ́lì lò jọ ti Ìsíkíẹ́lì òun Ẹ́sírà, kò sì dà bí ti àwọn ìwé ajẹmọ́-àròkọ bí Ecclesiasticus tí a kọ lẹ́yìn ìgbà náà. Ní ti lílò tí Dáníẹ́lì lo èdè Árámáíkì, gbé àkọsílẹ̀ méjì tí a ṣàwárí láàárín àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú yẹ̀ wò. Èdè Árámáíkì ni a fi kọ àwọn pẹ̀lú, ìgbà tí a kọ wọ́n sì jẹ́ láti ọ̀rúndún kìíní sí ìkejì ṣááju Sànmánì Tiwa—láìpẹ́ sí ìgbà tí wọ́n sọ pé a hùmọ̀ ìwé Dáníẹ́lì. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ti ṣàkíyèsí ìyàtọ̀ tí ó pọ̀ gan-an láàárín èdè Árámáíkì tí ó wà nínú àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí àti èyí tí ó wà nínú Dáníẹ́lì. Nípa báyìí, àwọn kan dábàá pé ọjọ́ ìwé Dáníẹ́lì ti ní láti fi ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún jìnnà sẹ́yìn ju bí àwọn olùṣelámèyítọ́ rẹ̀ ṣe kéde lọ.

Ní ti àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì “tí ó ṣòro” nínú Dáníẹ́lì ńkọ́? A ti ṣàwárí pé àwọn kan lára ìwọ̀nyí kì í ṣe èdè Gíríìkì rárá, èdè Páṣíà ni! Kìkì àwọn ọ̀rọ̀ tí a ṣì rò pé ó jẹ́ èdè Gíríìkì ni orúkọ àwọn ohun èlò orin mẹ́ta. Ǹjẹ́ wíwà tí àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́ta wọ̀nyí wà níbẹ̀ ha béèrè pé kí ó jẹ́ pé ìgbà pípẹ́ lẹ́yìn èyí tí ó sọ ni a kọ̀wé Dáníẹ́lì bí? Rárá. Àwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣàwárí pé àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn Gíríìkì ti ń nípa lórí àwọn ènìyàn fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún kí Gíríìsì tó di agbára ayé. Síwájú sí i, ká ní ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti èdè àwọn Gíríìkì gbòde kan ni a kọ ìwé Dáníẹ́lì ni, ṣé kìkì ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì mẹ́ta péré ni yóò wà nínú rẹ̀ ni? Ó ṣòro. Yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ ní jù bẹ́ẹ̀ lọ dáadáa. Nítorí náà, ẹ̀rí tí ó tinú èdè wá ti ìjóòótọ́ ìwé Dáníẹ́lì lẹ́yìn gidi gan-an ni.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

(Òkè) Ìṣògo Nebukadinésárì nípa àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé rẹ̀ ni ó wà nínú àkọsílẹ̀ yìí

(Ìsàlẹ̀) Ọ̀pá alámọ̀ rìbìtì kan nínú tẹ́ńpìlì ní Bábílónì dárúkọ Nábónídọ́sì Ọba àti Bẹliṣásárì ọmọkùnrin rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Ìtàn Nábónídọ́sì ṣe wí, àwọn ọmọ ogun Kírúsì wọnú Bábílónì láìsí ìjà ogun

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

(Apá ọ̀tún) “Àkọsílẹ̀ Lẹ́sẹẹsẹ ti Nábónídọ́sì” ròyìn pé Nábónídọ́sì fi ìṣàkóso síkàáwọ́ àkọ́bí rẹ̀

(Apá òsì) Àkọsílẹ̀ ti Bábílónì nípa bí Nebukadinésárì ṣe gbé ogun ja Júdà