Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Dídá Àwọn Olùjọsìn Tòótọ́ mọ̀ ní Àkókò Òpin

Dídá Àwọn Olùjọsìn Tòótọ́ mọ̀ ní Àkókò Òpin

Orí Kẹtàdínlógún

Dídá Àwọn Olùjọsìn Tòótọ́ mọ̀ ní Àkókò Òpin

1. Gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì orí Keje ṣe sọ, àwọn ohun àrà ọ̀tọ̀ wo ni ó fẹ́ ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ wa sí àwùjọ ènìyàn kéréje kan tí kò ní ohun ìgbèjà?

ÒGBÓǸTARÌGÌ agbára ayé kan dojú ìkọlù kíkankíkan kọ àwùjọ ènìyàn kéréje kan tí kò ní ohun ìgbèjà. Wọ́n là á já láìfarapa, kódà àmúdọ̀tun tún bá ìgbòkègbodò wọn—kì í ṣe nítorí agbára tí wọ́n ní bí kò ṣe nítorí pé wọ́n ṣeyebíye lójú Jèhófà Ọlọ́run. Dáníẹ́lì orí keje ti sàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, tí wọ́n wáyé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún. Àmọ́, ta tilẹ̀ ni àwọn wọ̀nyí? Orí kan náà yìí nínú Dáníẹ́lì tún sọ pé wọ́n jẹ́ “àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ,” Jèhófà Ọlọ́run. Ó tún fi hàn pé àwọn ẹni wọ̀nyí yóò tún di alájùmọ̀ṣàkóso nínú Ìjọba Mèsáyà nígbẹ̀yìn gbẹ́yín!—Dáníẹ́lì 7:13, 14, 18, 21, 22, 25-27.

2. (a) Irú ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹni àmì òróró? (b) Ipa ọ̀nà ọgbọ́n wo ni ó yẹ kí a tọ̀ ní àwọn àkókò wọ̀nyí?

2 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ́ nínú Dáníẹ́lì orí kọkànlá, òpin pátápátá máa dé bá ọba àríwá lẹ́yìn tí ó bá ti halẹ̀ mọ́ ilẹ̀ tẹ̀mí aláìléwu tí àwọn olùṣòtítọ́ wọ̀nyí wà. (Dáníẹ́lì 11:45; fi wé Ìsíkíẹ́lì 38:18-23.) Dájúdájú, Jèhófà ń dáàbò bo àwọn ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́ rẹ̀ wọ̀nyí gidigidi. Sáàmù 105:14, 15 sọ fún wa pé: “[Jèhófà] fi ìbáwí tọ́ àwọn ọba sọ́nà ní tìtorí wọn, pé: ‘Ẹ má fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi, ẹ má sì ṣe ohun búburú kankan sí àwọn wòlíì mi.’” Nígbà náà, ẹ kò ha gbà pé ní àwọn àkókò oníhílàhílo yìí, yóò bọ́gbọ́n mu pé kí àwọn “ogunlọ́gọ̀” tí ń pọ̀ sí i yìí fà mọ́ àwọn ẹni mímọ́ wọ̀nyí tímọ́tímọ́ gan-an bí? (Ìṣípayá 7:9; Sekaráyà 8:23) Ohun tí Jésù Kristi sọ pé kí àwọn ẹni bí àgùntàn ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn—pé kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́ nípa gbígbárùkù tì wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ wọn.—Mátíù 25:31-46; Gálátíà 3:29.

3. (a) Èé ṣe tí kò fi rọrùn láti wá àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù rí kí a sì fà mọ́ wọn pẹ́kípẹ́kí? (b) Báwo ni Dáníẹ́lì orí kejìlá yóò ṣe ṣèrànwọ́ nínú ọ̀ràn yìí?

3 Ṣùgbọ́n, Sátánì, Elénìní Ọlọ́run, ti fi gbogbo agbára rẹ̀ gbógun ti àwọn ẹni àmì òróró. Ó gbé ẹ̀sìn èké lárugẹ, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ayédèrú Kristẹni kún inú ayé dẹ́múdẹ́mú. Nítorí èyí, a ti ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lọ́nà. Ṣe ni àwọn mìíràn kàn kúkú sọ̀rètí nù pé àwọn kò lè wá àwọn tí ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ rí mọ́ láé. (Mátíù 7:15, 21-23; Ìṣípayá 12:9, 17) Kódà ó di dandan pé kí àwọn tí wọ́n ti wá “agbo kékeré” náà rí, tí wọ́n sì ti dara pọ̀ mọ́ wọn, sapá gidigidi láti lè máa bá ìgbàgbọ́ wọn lọ, nítorí pé ṣe ni ayé yìí ń sapá lemọ́lemọ́ láti jin ìgbàgbọ́ wọn lẹ́sẹ̀. (Lúùkù 12:32) Ìwọ ńkọ́? Ṣé o ti wá “àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ” rí, ṣé o sì ti ń dara pọ̀ mọ́ wọn? Ṣé o mọ àwọn ẹ̀rí dídájú hán-únhán-ún tí ó ń fi hàn pé àwọn tí o rí jẹ́ àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run yàn ní ti gidi? Irú ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ lè túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun. Ó sì tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ kí o lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn láti rí àṣírí ìdàrúdàpọ̀ inú ẹ̀sìn ayé òde òní. Ibú ìmọ̀ tí ń gbẹ̀mí là yìí wà nínú Dáníẹ́lì orí kejìlá.

ỌMỌ ALÁDÉ ŃLÁ NÁÀ BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ NÍ PẸRẸU

4. (a) Ohun méjì pàtó wo ni Dáníẹ́lì 12:1 sọ tẹ́lẹ̀ nípa Máíkẹ́lì? (b) Nínú Dáníẹ́lì, kí ni a sábà máa ń ní lọ́kàn tí a bá sọ pé ọba kan “dúró”?

4 Dáníẹ́lì 12:1 kà pé: “Ní àkókò yẹn, Máíkẹ́lì yóò dìde dúró, ọmọ aládé ńlá tí ó dúró nítorí àwọn ọmọ àwọn ènìyàn rẹ.” Ẹsẹ yìí sàsọtẹ́lẹ̀ nǹkan méjì pàtó yìí nípa Máíkẹ́lì: èkíní, pé “ó dúró,” èyí tí ó ń dábàá ipò àwọn nǹkan tí ó wà fún àkókò gígùn kan; èkejì, pé “yóò dìde dúró,” èyí tí ó dábàá ti pé ìṣẹ̀lẹ̀ kan yóò ṣẹlẹ̀ láàárín sáà náà. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a fẹ́ mọ sáà tí Máíkẹ́lì “dúró nítorí àwọn ọmọ àwọn ènìyàn [Dáníẹ́lì].” Rántí pé Máíkẹ́lì jẹ́ orúkọ tí a fi fún Jésù nítorí ipa tí ó ń kó gẹ́gẹ́ bí Olùṣàkóso ti ọ̀run. Títọ́ka tí a tọ́ka sí i pé “ó dúró” rán wa létí ọ̀nà tí a gbà lo gbólóhùn yìí níbòmíràn nínú ìwé Dáníẹ́lì. Ó sábà máa ń tọ́ka sí ìgbésẹ̀ ọba kan, irú bí ìgbà tó bá gba agbára gẹ́gẹ́ bí ọba.—Dáníẹ́lì 11:2-4, 7, 20, 21.

5, 6. (a) Àkókò wo ni Máíkẹ́lì dúró? (b) Ìgbà wo ni Máíkẹ́lì “dìde dúró,” báwo ni ó ṣe “dìde dúró,” kí sì ni àbáyọrí rẹ̀?

5 Ó hàn gbangba pé àkókò kan tí a sọ ní pàtó níbòmíràn nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ni áńgẹ́lì yìí ń tọ́ka sí. Jésù pè é ní “wíwà níhìn-ín” (lédè Gíríìkì, pa·rou·si’a) òun, nígbà tí òun yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba ní ọ̀run. (Mátíù 24:37-39) Àkókò yìí ni a tún pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” àti “àkókò òpin.” (2 Tímótì 3:1; Dáníẹ́lì 12:4, 9) Láti ìgbà tí sáà yẹn ti bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 ni Máíkẹ́lì ti dúró gẹ́gẹ́ bí Ọba ní ọ̀run.—Fi wé Aísáyà 11:10; Ìṣípayá 12:7-9.

6 Ṣùgbọ́n, ìgbà wo ni Máíkẹ́lì “dìde dúró”? Ìgbà tí ó dìde láti gbé ìgbésẹ̀ àkànṣe kan ni. Ọjọ́ iwájú ni Jésù yóò ṣe èyí. Lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀, Ìṣípayá 19:11-16 ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà Ọba alágbára kan tí ń gẹṣin lọ ní ìwájú agbo àwọn áńgẹ́lì ọmọ ogun, tí ó sì ń mú ìparun bá àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. Dáníẹ́lì 12:1 ń bá a lọ pé: “Dájúdájú, àkókò wàhálà yóò wáyé irú èyí tí a kò tíì mú kí ó wáyé rí láti ìgbà tí orílẹ̀-èdè ti wà títí di àkókò yẹn.” Gẹ́gẹ́ bí Olórí Amúdàájọ́ṣẹ ti Jèhófà, Kristi yóò mú gbogbo ètò àwọn nǹkan burúkú yìí wá sópin nígbà “ìpọ́njú ńlá” tí a sọ tẹ́lẹ̀ náà.—Mátíù 24:21; Jeremáyà 25:33; 2 Tẹsalóníkà 1:6-8; Ìṣípayá 7:14; 16:14, 16.

7. (a) Ìrètí wo ni ó wà fún gbogbo olùṣòtítọ́ nígbà “àkókò wàhálà” tí ń bọ̀ náà? (b) Kí ni ìwé Jèhófà, èé sì ti ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí a wà nínú rẹ̀?

7 Báwo ni nǹkan yóò ti rí fún àwọn tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ ní àkókò ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ yìí? A sọ fún Dáníẹ́lì síwájú sí i pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn ènìyàn rẹ yóò sá àsálà, olúkúlùkù ẹni tí a rí tí a kọ sílẹ̀ nínú ìwé náà.” (Fi wé Lúùkù 21:34-36.) Kí ni ìwé yìí? Ní ṣókí, ó dúró fún rírántí tí Jèhófà Ọlọ́run rántí àwọn tí wọ́n ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Málákì 3:16; Hébérù 6:10) Àwọn tí a kọrúkọ wọn sínú ìwé ìyè yìí ló wà láàbò jù lọ láyé yìí, nítorí abẹ́ ààbò àtọ̀runwá ni wọ́n wà. Ìpalára yòówù kí a ṣe sí wọn, a lè ṣe àtúnṣe rẹ̀, a óò sì ṣe é. Kódà bí ikú bá pa wọ́n kí “àkókò wàhálà” tí ń bọ̀ yìí tó dé, wọ́n wà nípamọ́ nínú ìrántí Jèhófà tí kò lópin. Yóò rántí wọn yóò sì jí wọn dìde nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún ti Jésù Kristi.—Ìṣe 24:15; Ìṣípayá 20:4-6.

ÀWỌN ẸNI MÍMỌ́ “JÍ DÌDE”

8. Ìrètí amọ́kànyọ̀ wo ni Dáníẹ́lì 12:2 fi síwájú wa?

8 Ìrètí àjíǹde ń tuni nínú gidigidi. Dáníẹ́lì 12:2 mẹ́nu kàn án pé: “Ọ̀pọ̀ yóò sì wà nínú àwọn tí ó sùn nínú ekuru ilẹ̀ tí yóò jí dìde, àwọn wọ̀nyí sí ìyè tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin, àti àwọn wọ̀nyẹn sí ẹ̀gàn àti sí ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Fi wé Aísáyà 26:19.) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lè wá mú wa rántí ìlérí amóríyá tí Jésù Kristi ṣe nípa àjíǹde gbogbo àwọn ẹni tó bá yẹ láti jí dìde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 5:28, 29) Ìrètí yìí mà múni lára yá gágá o! Ṣáà ronú ná nípa àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé wa ọ̀wọ́n—tí wọ́n ti kú—pé a óò yọ̀ǹda fún wọn láti tún wà láàyè lọ́jọ́ iwájú! Àmọ́ o, oríṣi àjíǹde mìíràn—ọ̀kan tí ó ti ṣẹlẹ̀—ni ìlérí inú ìwé Dáníẹ́lì yìí ń tọ́ka sí ní pàtàkì. Báwo ló ṣe lè jẹ́ bẹ́ẹ̀?

9. (a) Èé ṣe tí ó fi bọ́gbọ́n mu láti retí pé kí Dáníẹ́lì 12:2 ní ìmúṣẹ nínú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn? (b) Irú àjíǹde wo ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ń tọ́ka sí, báwo ni a sì ṣe mọ̀?

9 Gbé àyíká ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò. Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe rí i, kì í ṣe kìkì ìparí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ni ọ̀rọ̀ Da orí kejìlá ẹsẹ kìíní kàn, ó tún kan gbogbo sáà àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ní ti gidi, kì í ṣe inú párádísè orí ilẹ̀ ayé tí ń bọ̀ ni èyí tí ó pọ̀ jù nínú orí yẹn yóò ti ní ìmúṣẹ bí kò ṣe ní àkókò òpin. Àjíǹde kankan ha ṣẹlẹ̀ láàárín sáà yìí bí? Ní tòótọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé àjíǹde “àwọn tí ó jẹ́ ti Kristi” wáyé “nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀.” Àmọ́, àjíǹde ti àwọn tí a jí dìde sí ọ̀run jẹ́ ti “àìlèdíbàjẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:23, 52) Kò sí ìkankan nínú wọn tí a jí dìde “sí ẹ̀gàn àti sí ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin” tí Dáníẹ́lì 12:2 sọ tẹ́lẹ̀. Ṣé oríṣi àjíǹde mìíràn wá wà ni? Nínú Bíbélì, nígbà mìíràn àjíǹde lè ní ìtumọ̀ tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àyọkà alásọtẹ́lẹ̀ wà nínú Ìsíkíẹ́lì àti Ìṣípayá, tó jẹ́ pé ìmúsọjí tàbí àjíǹde tẹ̀mí ni wọ́n tọ́ka sí.—Ìsíkíẹ́lì 37:1-14; Ìṣípayá 11:3, 7, 11.

10. (a) Ní ọ̀nà wo ni a fi jí àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró dìde ní àkókò òpin? (b) Síbẹ̀síbẹ̀, báwo ni àwọn kan lára àwọn ẹni àmì òróró ṣe jíǹde sí “ẹ̀gàn àti sí ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin”?

10 Irú ìmúsọjí nípa tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ ha ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run ní àkókò òpin bí? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ohun tí ìtàn kúkú fi hàn pé ó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1918 ni pé a gbógun ti àwùjọ kéréje àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró ti àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ lọ́nà tí ó bùáyà tí a fi ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ ìsìn àfètòṣe tí wọ́n ń ṣe láwùjọ. Àmọ́, lọ́dún 1919, wọ́n sọjí padà lọ́nà tẹ̀mí, lódìkejì sí àròpin àwọn ènìyàn. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí bá àpèjúwe àjíǹde tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 12:2 mu. Àwọn kan “jí dìde” nípa tẹ̀mí ní àkókò náà àti lẹ́yìn náà. Ṣùgbọ́n, ó bani nínú jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo wọn ló ń bá a lọ láti wà láàyè nípa tẹ̀mí. Àwọn tó jẹ́ pé lẹ́yìn tí a jí wọn dìde, wọ́n yàn láti kọ Mèsáyà Ọba sílẹ̀ tí wọ́n sì fi iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run sílẹ̀, ti fúnra wọn yan ‘ẹ̀gàn àti ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin’ tí a ṣàpèjúwe nínú Dáníẹ́lì 12:2. (Hébérù 6:4-6) Ṣùgbọ́n, bí àwọn ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́ ti ń lo sísọjí tí wọ́n sọjí nípa tẹ̀mí lọ́nà rere, wọ́n fi ìṣòtítọ́ gbárùkù ti Mèsáyà Ọba. Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe sọ, ìṣòtítọ́ wọn sìn wọ́n lọ sí “ìyè tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Lónìí, títa tí wọ́n ń ta kébé nípa tẹ̀mí láìfi àtakò pè, ń ràn wá lọ́wọ́ láti dá wọn mọ̀.

WỌ́N ‘Ń TÀN BÍ ÌRÀWỌ̀’

11. Àwọn wo ni “àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye” lónìí, lọ́nà wo sì ni wọ́n gbà ń tàn bí ìràwọ̀?

11 Ẹsẹ méjì tó tẹ̀ lé e nínú Dáníẹ́lì orí kejìlá tilẹ̀ tún ṣèrànwọ́ síwájú sí i fún wa láti dá “àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ” mọ̀ yàtọ̀. Ní ẹsẹ kẹta, áńgẹ́lì náà sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò sì máa tàn bí ìtànyòò òfuurufú; àwọn tí wọ́n sì ń mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo yóò máa tàn bí ìràwọ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” Àwọn wo ni “àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye” lónìí? “Àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ” kan náà ni ẹ̀rí tún tọ́ka sí. Ó ṣe tán, yàtọ̀ sí àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́, ta ló tún ní ìjìnlẹ̀ òye láti fòye mọ̀ pé Máíkẹ́lì, Ọmọ Aládé Ńlá náà, bẹ̀rẹ̀ sí dúró gẹ́gẹ́ bí Ọba ní ọdún 1914? Nípa wíwàásù irú àwọn òtítọ́ bí èyí—àti nípa híhùwà lọ́nà ti Kristẹni—wọ́n “ń tàn bí atànmọ́lẹ̀” nínú ayé tí ó ṣókùnkùn nípa tẹ̀mí yìí. (Fílípì 2:15; Jòhánù 8:12) Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa wọn pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn olódodo yóò máa tàn yòò bí oòrùn nínú ìjọba Baba wọn.”—Mátíù 13:43.

12. (a) Ní àkókò òpin, báwo ni àwọn ẹni àmì òróró ṣe ń lọ́wọ́ nínú ‘mímú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo’? (b) Báwo ni àwọn ẹni àmì òróró yóò ṣe mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo tí wọn yóò sì ‘tàn bí ìràwọ̀’ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi?

12 Kódà, Dáníẹ́lì 12:3 tilẹ̀ tún sọ iṣẹ́ tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyí yóò máa ṣe ní àkókò òpin fún wa. Wọn yóò máa “mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo.” Àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró wá bẹ̀rẹ̀ sí kó ìyókù àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, àwọn àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi jọ. (Róòmù 8:16, 17; Ìṣípayá 7:3, 4) Nígbà tí iṣẹ́ yẹn parí—ó dájú pé ó jẹ́ ní nǹkan bí àárín àwọn ọdún 1930—wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kó “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” jọ. (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16) Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Nítorí náà, wọ́n wà ní ipò mímọ́ lójú Jèhófà. Lónìí, iye wọn ń lọ sí àràádọ́ta ọ̀kẹ́, ìrètí pé wọn yóò la ìparun ayé burúkú yìí já jẹ́ ìdùnnú fún wọn. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Jésù àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jọ jẹ́ ọba àti àlùfáà yóò mú àǹfààní ìràpadà náà lò ní kíkún fún aráyé onígbọràn lórí ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣèrànwọ́ fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ láti bọ́ kúrò lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ó bá jẹ mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá láti ọ̀dọ̀ Ádámù. (2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 7:13, 14; 20:5, 6) Nígbà yẹn, àwọn ẹni àmì òróró yóò máa kópa nínú ‘mímú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo,’ wọn yóò sì máa ‘tàn bí ìràwọ̀’ ojú ọ̀run ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn. O ha ka ìrètí gbígbé lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ ìjọba ọ̀run ológo ti Kristi àti àwọn alábàáṣàkóso rẹ̀ sí iyebíye bí? Ẹ wo bí ó ti jẹ́ àǹfààní ńláǹlà tó láti máa bá “àwọn ẹni mímọ́” lọ́wọ́ nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run!—Mátíù 24:14.

WỌ́N “LỌ KÁÀKIRI”

13. Ní ọ̀nà wo ni a gbà fèdìdì di àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì tí a sì mú kí ó wà ní àṣírí?

13 Ohun tí áńgẹ́lì náà polongo fún Dáníẹ́lì, èyí tí ó ti bẹ̀rẹ̀ láti Dáníẹ́lì 10:20, wá fi ọ̀rọ̀ amúnilọ́kànyọ̀ wọ̀nyí parí rẹ̀ pé: “Àti ní ti ìwọ, Dáníẹ́lì, ṣe àwọn ọ̀rọ̀ náà ní àṣírí, kí o sì fi èdìdì di ìwé náà, títí di àkókò òpin. Ọ̀pọ̀ yóò máa lọ káàkiri, ìmọ̀ tòótọ́ yóò sì di púpọ̀ yanturu.” (Dáníẹ́lì 12:4) Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ohun tí a mí sí Dáníẹ́lì láti kọ sílẹ̀ ni a mú kí ó wà ní àṣírí tí a sì fèdìdì dì ní tòótọ́ tí ènìyàn kò fi lóye wọn. Kódà, Dáníẹ́lì alára kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Wàyí o, ní tèmi, mo gbọ́, ṣùgbọ́n èmi kò lóye.” (Dáníẹ́lì 12:8) Lọ́nà yìí, ìwé Dáníẹ́lì wà lábẹ́ ìfèdìdìdì fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Ọjọ́ òní wá ńkọ́?

14. (a) Nígbà “àkókò òpin,” ta ló ń “lọ káàkiri,” nínú ibo sì ni? (b) Ẹ̀rí wo ló wà pé Jèhófà ti bù kún ‘lílọ káàkiri’ yìí?

14 Àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti máa gbé ní “àkókò òpin” tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú ìwé Dáníẹ́lì. Bí a ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ni wọ́n ti “lọ káàkiri” nínú àwọn ojú ìwé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí ni àbájáde rẹ̀? Pẹ̀lú ìbùkún Jèhófà, ìmọ̀ tòótọ́ ti di púpọ̀ rẹpẹtẹ. A ti fi ìjìnlẹ̀ òye jíǹkí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́, èyí mú kí ó ṣeé ṣe fún wọn láti lóye pé Ọmọ ènìyàn di Ọba lọ́dún 1914, láti dá àwọn ẹranko ẹhànnà inú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì mọ̀ yàtọ̀, láti ṣe kìlọ̀kìlọ̀ nípa “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro”—ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ díẹ̀. (Dáníẹ́lì 11:31) Nígbà náà, ọ̀pọ̀ yanturu ìmọ̀ tòótọ́ yìí tún jẹ́ àmì mìíràn tí a fi lè dá “àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ” mọ̀ yàtọ̀. Àmọ́ Dáníẹ́lì tún gba ẹ̀rí síwájú sí i.

A ‘FỌ́ WỌN TÚÚTÚÚ’

15. Ìbéèrè wo ni áńgẹ́lì kan wá béèrè báyìí, ta sì ni ìbéèrè yìí lè mú wa rántí?

15 A lè rántí pé bèbè “odò ńlá náà,” Hídẹ́kẹ́lì, tí a tún mọ̀ sí Tígírísì ni Dáníẹ́lì ti rí àwọn ìhìn iṣẹ́ yìí gbà láti ọ̀dọ̀ áńgẹ́lì. (Dáníẹ́lì 10:4) Wàyí o, ó rí àwọn ẹ̀dá mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ áńgẹ́lì, ó sì sọ pé: “Mo sì wò, èmi Dáníẹ́lì, sì kíyè sí i! àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan ní ìhín bèbè ìṣàn omi, èkejì ní ọ̀hún bèbè ìṣàn omi. Nígbà náà ni ọ̀kan sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, tí ó wà lórí ìṣàn omi pé: ‘Báwo ni yóò ti pẹ́ tó kí a tó dé òpin àwọn ohun àgbàyanu yìí?’” (Dáníẹ́lì 12:5, 6) Ìbéèrè tí áńgẹ́lì náà béèrè níhìn-ín lè tún mú wa rántí “àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ.” Ní ìbẹ̀rẹ̀ “àkókò òpin,” lọ́dún 1914, wọ́n ń ṣàníyàn gidigidi lórí ìbéèrè nípa báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó kí àwọn ìlérí Ọlọ́run tó ní ìmúṣẹ. Ìdáhùn ìbéèrè yìí mú kí ó hàn kedere pé àwọn gan-an ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń bá wí ní tààràtà.

16. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni áńgẹ́lì náà sọ, báwo ni ó sì ṣe tẹnu mọ́ dídájú tí ìmúṣẹ rẹ̀ dájú?

16 Àkọsílẹ̀ Dáníẹ́lì ń bá a lọ pé: “Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ti ọkùnrin tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, ẹni tí ó wà lórí ìṣàn omi, bí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀ sókè ọ̀run, tí ó sì fi Ẹni tí ó wà láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin búra pé: ‘Yóò jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀, àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ àti ààbọ̀. Àti ní kété tí fífọ́ agbára àwọn ènìyàn mímọ́ túútúú bá ti parí, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò wá sí òpin.’” (Dáníẹ́lì 12:7) Ọ̀ràn tó gbàrònú mà lèyí o. Áńgẹ́lì náà gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè ní ìbúra, bóyá kí ó fi lè ṣeé ṣe fún àwọn áńgẹ́lì méjèèjì tó wà níhà méjèèjì odò fífẹ̀ náà láti lè rí ìfaraṣàpèjúwe rẹ̀. Ó wá tipa báyìí tẹnu mọ́ bí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe dáni lójú hán-únhán-ún tó. Àmọ́ o, ìgbà wo ni àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ wọ̀nyí? Wíwá ìdáhùn rẹ̀ rí kò ṣòro tó bí o ṣe lè rò.

17. (a) Àwọn ohun tí ó jọra wo ni a lè rí nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí a kọ sínú Dáníẹ́lì 7:25, Dáníẹ́lì 12:7, àti Ìṣípayá 11:3, 7, 9? (b) Báwo ni àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀ náà ṣe gùn tó?

17 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí jọ àsọtẹ́lẹ̀ méjì mìíràn lọ́nà tí ó gbàfiyèsí. Ọ̀kan, tí a gbé yẹ̀ wò ní Orí Kẹsàn-án ìwé yìí, wà nínú Dáníẹ́lì 7:25; ìkejì sì wà ní Ìṣípayá 11:3, 7, 9. Ṣàkíyèsí bí wọ́n ṣe jọra wọn. Àwọn méjèèjì ní ìmúṣẹ ní àkókò òpin. Àsọtẹ́lẹ̀ méjèèjì jẹ́ nípa àwọn ìránṣẹ́ mímọ́ ti Ọlọ́run, ó fi wọ́n hàn pé a ṣe inúnibíni sí wọn, pé fún ìgbà kúkurú kan, wọ́n kò tilẹ̀ lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n máa ń ṣe fáráyé. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àsọtẹ́lẹ̀ náà fi hàn pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run sọjí, wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ lékè àwọn ọ̀tá wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àsọtẹ́lẹ̀ náà sì mẹ́nu kan bí àkókò tí ìnira bá àwọn ẹni mímọ́ wọ̀nyí ṣe gùn tó. Àsọtẹ́lẹ̀ méjèèjì nínú Dáníẹ́lì (7:25 àti 12:7) tọ́ka sí ‘àkókò kan, àwọn àkókò, àti ààbọ̀ àkókò.’ Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ní gbogbo gbòò kà á sí pé èyí túmọ̀ sí àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀. Ìṣípayá tọ́ka sí sáà kan náà gẹ́gẹ́ bí oṣù méjìlélógójì, tàbí ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà [1,260] ọjọ́. (Ìṣípayá 11:2, 3) Èyí jẹ́rìí sí i pé àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀ inú Dáníẹ́lì tọ́ka sí ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ nínú èyí tí ọdún kọ̀ọ̀kan ti ní òjìdín-nírínwó [360] ọjọ́ nínú. Ṣùgbọ́n ìgbà wo ni ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà ọjọ́ wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀?

18. (a) Gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì 12:7 ṣe wí, kí ni yóò jẹ́ àmì pé ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà ọjọ́ ti dópin? (b) Ìgbà wo ni a wá fọ́ “agbára àwọn ènìyàn mímọ́ túútúú” níkẹyìn, báwo ni èyí sì ṣe ṣẹlẹ̀? (d) Ìgbà wo ni ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà ọjọ́ yẹn bẹ̀rẹ̀, báwo ni àwọn ẹni àmì òróró sì ṣe ‘sọ tẹ́lẹ̀ ní wíwọ aṣọ àpò ìdọ̀họ’ láàárín àkókò náà?

18 Àlàyé àsọtẹ́lẹ̀ náà kún rẹ́rẹ́ ní ti ìgbà wo ni ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà ọjọ́ náà yóò parí—ìgbà tí “fífọ́ agbára àwọn ènìyàn mímọ́ túútúú bá ti parí.” Láàárín ọdún 1918, a fẹ̀sùn èké kan àwọn ẹni sàràkí-sàràkí nínú àjọ Watch Tower Bible and Tract Society, títí kan J. F. Rutherford alága rẹ̀, a dájọ́ àhámọ́ ọlọ́jọ́ gbọọrọ fún wọn, a sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Lóòótọ́, àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run fojú rí i pé a ‘fọ́’ iṣẹ́ wọn “túútúú,” tí a ṣẹ́ agbára wọn. Bí a bá ṣírò ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ padà sẹ́yìn láti ìdajì ọdún 1918, yóò mú wa dé òpin ọdún 1914. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ńṣe ni àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ àwùjọ kéréje ń gbára dì fún fífojúwiná inúnibíni. Ogun Àgbáyé Kìíní ti bẹ́ sílẹ̀, àtakò sí iṣẹ́ wọn sì túbọ̀ ń le sí i. Lọ́dún 1915, wọ́n tilẹ̀ gbé ẹsẹ ọdọọdún wọn karí ìbéèrè yìí tí Kristi bi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin lè mu nínú aago tí èmi ó mu?” (Mátíù 20:22, Bibeli Mimọ) Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ nínú Ìṣípayá 11:3, sáà ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e jẹ́ àkókò ọ̀fọ̀ fún àwọn ẹni àmì òróró—àfi bí ẹni pé ṣe ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ ní wíwọ aṣọ àpò ìdọ̀họ. Ṣe ni inúnibíni túbọ̀ le koko sí i. A ju àwọn kan lára wọn sẹ́wọ̀n, a wọ́jọ pọ̀ kọ lu àwọn mìíràn, a sì tún dá àwọn mìíràn lóró pẹ̀lú. Kíkú tí C. T. Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ ti Society kú lọ́dún 1916, bu ìrẹ̀wẹ̀sì lu ọ̀pọ̀lọpọ̀. Àmọ́ kí ni yóò wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí àkókò ṣíṣú dùdù yìí bá wá sí ìparí rẹ̀ nípa pípa tí a óò pa àwọn ènìyàn mímọ́ wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ oníwàásù?

19. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà nínú Ìṣípayá orí kọkànlá ṣe mú un dá wa lójú pé a kò ní pa àwọn ẹni àmì òróró lẹ́nu mọ́ fún ìgbà pípẹ́ títí?

19 Àsọtẹ́lẹ̀ irú rẹ̀ tí ó wà nínú Ìṣípayá 11:3, 9, 11 fi hàn pé lẹ́yìn tí a pa ‘àwọn ẹlẹ́rìí méjèèjì,’ ìwọ̀nba ìgbà kúkúrú—ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀—ni wọ́n fi wà ní òkú, kí a tó mú wọn sọjí. Bákan náà, àsọtẹ́lẹ̀ inú Dáníẹ́lì orí kejìlá fi hàn pé àwọn ènìyàn mímọ́ kì yóò pa ẹnu mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ púpọ̀ sí i ṣì ń bẹ níwájú fún wọn.

A ‘WẸ̀ WỌ́N MỌ́, WỌ́N DI FUNFUN, A SÌ YỌ́ WỌN MỌ́’

20. Gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì 12:10 ṣe sọ, àwọn ìbùkún wo ni yóò dé sórí àwọn ẹni àmì òróró lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fojú winá inúnibíni líle koko tán?

20 Bí a ti ṣe sọ ṣáájú, Dáníẹ́lì kọ àwọn nǹkan wọ̀nyí sílẹ̀ ṣùgbọ́n kò lóye wọn. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ti ní láti máa dà á rò pé ṣe àwọn ènìyàn mímọ́ yóò wá ti ọwọ́ àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí wọn pa run pátápátá ni, nítorí ó béèrè pé, “Kí ni yóò jẹ́ apá ìgbẹ̀yìn nǹkan wọ̀nyí?” Áńgẹ́lì náà dáhùn pé: “Máa lọ, Dáníẹ́lì, nítorí pé a ṣe ọ̀rọ̀ náà ní àṣírí, a sì fi èdìdì dì í títí di àkókò òpin. Ọ̀pọ̀ yóò wẹ ara wọn mọ́, wọn yóò sì sọ ara wọn di funfun, a ó sì yọ́ wọn mọ́. Dájúdájú, àwọn ẹni burúkú yóò máa gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà burúkú, àwọn ẹni burúkú kankan kì yóò sì lóye; ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò lóye.” (Dáníẹ́lì 12:8-10) Ìrètí tí ó dájú ń bẹ fún àwọn ènìyàn mímọ́! Dípò tí wọn yóò fi di ẹni tí a pa run, ṣe ni a óò sọ wọ́n di funfun, tí a óò bù kún wọn nípa kíkà wọ́n sí ẹni tí ó wà ní ipò mímọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run. (Málákì 3:1-3) Ìjìnlẹ̀ òye wọn nípa àwọn ohun tẹ̀mí yóò jẹ́ kí wọ́n lè máa wà ní mímọ́ lójú Ọlọ́run. Lọ́nà tó yàtọ̀, àwọn ẹni burúkú yóò kọ̀ láti lóye àwọn ohun tẹ̀mí. Àmọ́, ìgbà wo ni gbogbo ìwọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀?

21. (a) Àkókò tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 12:11 yóò bẹ̀rẹ̀ nígbà tí a bá mú kí ipò àwọn nǹkan wo wáyé? (b) Kí ni “apá pàtàkì ìgbà gbogbo,” ìgbà wo ni a sì mú un kúrò? (Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 298.)

21 A sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Láti ìgbà tí a ti mú apá pàtàkì ìgbà gbogbo kúrò, tí a sì ti gbé ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro kalẹ̀, yóò jẹ́ àádọ́rùn-ún lé ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́.” Nípa báyìí, ìgbà tí a bá mú kí ipò àwọn nǹkan pàtó kan wáyé ni sáà yìí yóò tó bẹ̀rẹ̀. A óò ní láti mú “apá pàtàkì ìgbà gbogbo”—tàbí “ẹbọ tí ń bá a lọ láìdáwọ́dúró” *—kúrò. (Dáníẹ́lì 12:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Ẹbọ wo ni áńgẹ́lì yìí ní lọ́kàn? Kì í ṣe àwọn ẹbọ tí a máa ń fi ẹran rú nínú tẹ́ńpìlì èyíkéyìí lórí ilẹ̀ ayé. Kódà, tẹ́ńpìlì tí ó tilẹ̀ fìgbà kan wà ní Jerúsálẹ́mù rí pàápàá, kàn “jẹ́ ẹ̀dà ti òtítọ́” ni, ẹ̀dà tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ti Jèhófà, tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹrẹu nígbà tí Kristi di Àlùfáà Àgbà tẹ́ńpìlì náà lọ́dún 29 Sànmánì Tiwa! Nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yìí, tí ó dúró fún ìṣètò tí Ọlọ́run ṣe fún ìjọsìn mímọ́ gaara, kò sídìí fún rírú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ títí lọ láìdáwọ́dúró, nítorí pé a ti “fi Kristi rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀.” (Hébérù 9:24-28) Síbẹ̀síbẹ̀, gbogbo Kristẹni tòótọ́ ní ń rúbọ nínú tẹ́ńpìlì yìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nípasẹ̀ [Kristi], ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 13:15) Nípa báyìí, ipò àkọ́kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí—mímú “apá pàtàkì ìgbà gbogbo” kúrò—wáyé ní ìdajì ọdún 1918, nígbà tí a fẹ́rẹ̀ẹ́ pa iṣẹ́ wíwàásù tì.

22. (a) Kí ni “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro,” ìgbà wo ni a sì fi í lọ́lẹ̀? (b) Ìgbà wo ni àkókò tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 12:11 bẹ̀rẹ̀, ìgbà wo ni ó sì parí?

22 Àmọ́, ipò kejì—ìfilọ́lẹ̀ tàbí ‘gbígbé ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro kalẹ̀’—wá ńkọ́? Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú ìjíròrò wa nínú Dáníẹ́lì 11:31, ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro yẹn jẹ́ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lákọ̀ọ́kọ́, ó sì wá jáde wá gẹ́gẹ́ bí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lẹ́yìn náà. Àwọn méjèèjì jẹ́ ohun ìríra ní ti pé a polongo wọn pé àwọn nìkan ṣoṣo ni aráyé gbójú lé pé wọ́n lè mú àlàáfíà wá. Nípa báyìí, nínú ọkàn-àyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àyè Ìjọba Ọlọ́run ni àwọn àjọ wọ̀nyí gbà ní ti gidi! January 1919 ni a gbé àbá Ìmùlẹ̀ yìí jáde fáráyé. Nígbà náà, ní àkókò yẹn, a mú ipò méjèèjì tí a tọ́ka sí nínú Dáníẹ́lì 12:11 ṣẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, àádọ́rùn-ún lé ní ẹgbẹ̀fà [1,290] ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919, ó sì ń bá a lọ títí di ìgbà ìwọ́wé (ní Àríwá Ìlàjì Ayé) lọ́dún 1922.

23. Báwo ni àwọn ẹni mímọ́ Ọlọ́run ṣe tẹ̀ síwájú dórí wíwà ní ipò àwọn tí a wẹ̀ mọ́ láàárín àádọ́rùn-ún lé ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́ tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Dáníẹ́lì orí kejìlá?

23 Ní ìgbà yẹn, ǹjẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́ tẹ̀ síwájú láti lè di àwọn tí a sọ di funfun tí a sì wẹ̀ mọ́ lójú Ọlọ́run bí? Dájúdájú wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀! A dá ààrẹ Watch Tower Society àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní March 1919. Lẹ́yìn náà ni a wá sọ pé wọn kò jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn èké tí a fi kàn wọ́n. Bí wọ́n ṣe mọ̀ pé iṣẹ́ púpọ̀ ṣì ń bẹ fún wọn láti ṣe, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n sì ṣètò fún àpéjọpọ̀ kan ní September ọdún 1919. Ọdún yẹn kan náà ni a tẹ ẹ̀dà àkọ́kọ́ ìwé ìròyìn tí ó ṣèkejì Ilé Ìṣọ́ jáde. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pàá, a pè é ní The Golden Age (Jí! nísinsìnyí), ó ti jẹ́ alátìlẹyìn gbágbáágbá fún Ilé Ìṣọ́ nínú fífi àìṣojo táṣìírí ìwà ìbàjẹ́ ayé yìí àti nínú ríran àwọn ènìyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ láti máa wà ní mímọ́ nìṣó. Nígbà tí ó fi máa di òpin àádọ́rùn-ún lé ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́ tí a sọ tẹ́lẹ̀ náà, àwọn ènìyàn mímọ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di àwọn tí a wẹ̀ mọ́, wọ́n sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ sí ipò mímọ́ padà. Ní September 1922, ní nǹkan bí ìgbà tí sáà yìí fẹ́ parí gẹ́lẹ́, wọ́n ṣe àpéjọpọ̀ pàtàkì kan ní ìlú Cedar Point, Ohio, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ó fún ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù ní àlékún ìṣírí tó bùáyà. Ṣùgbọ́n, ó ṣì ń béèrè pé kí ìtẹ̀síwájú púpọ̀ sí i wà. Ìyẹn máa di ṣíṣe ní sáà àkànṣe tí yóò tẹ̀ lé e.

AYỌ̀ FÚN ÀWỌN ÈNÌYÀN MÍMỌ́

24, 25. (a) Kí ni àkókò tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 12:12, ìgbà wo sì ni ó dájú pé ó bẹ̀rẹ̀, ìgbà wo ni ó sì parí? (b) Báwo ni ipò tẹ̀mí ti àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró ṣe rí ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ẹ́dégbèje ọjọ́ ó lé márùndínlógójì náà?

24 Áńgẹ́lì Jèhófà fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí parí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa àwọn ẹni mímọ́ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà, tí ó sì dé ẹ̀ẹ́dégbèje ọjọ́ ó lé márùndínlógójì!” (Dáníẹ́lì 12:12) Áńgẹ́lì yẹn kò fúnni ní ojútùú ní ti ìgbà tí sáà yìí bẹ̀rẹ̀ àti ìgbà tí ó parí. Lójú bí ìtàn ìṣàkóso Ọlọ́run ṣe lọ, ó jọ pé kété lẹ́yìn sáà tí ó ṣáájú rẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀. A jẹ́ pé yóò bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ìwọ́wé ọdún 1922 títí dé ìgbà ìrúwé ọdún 1926 (ní Àríwá Ìlàjì Ayé). Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́ wà ní ipò ayọ̀ nígbà tí sáà náà fi parí bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ní àwọn ọ̀nà pàtàkì kan nípa tẹ̀mí.

25 Kódà lẹ́yìn àpéjọpọ̀ ní ọdún 1922 (tí a fi hàn ní ojú ìwé 302), àwọn kan lára àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run ṣì ń ṣàárò ìgbà tó ti kọjá. Pàtàkì ohun tí wọ́n ṣì ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìpàdé wọn ni Bíbélì àti ọ̀wọ́ ìtẹ̀jáde Studies in the Scriptures [Ìkẹ́kọ̀ọ́ Nínú Ìwé Mímọ́], tí C. T. Russell ṣe jáde. Ní ìgbà yẹn, ojú ìwòye tí ó gbilẹ̀ ń tọ́ka sí ọdún 1925 pé ọdún yẹn ni àjíǹde yóò wáyé tí a óò sì mú Párádísè padà bọ̀ sípò lórí ilẹ̀ ayé. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ló ń ṣe iṣẹ́ ìsìn tìtorí déètì pàtó kan tí wọ́n ti fọkàn sí. Àwọn kan fi ìgbéraga kọ̀ láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ wíwàásù fáráyé. Bí ipò nǹkan ṣe rí yìí kò máyọ̀ wá rárá.

26. Bí ẹ̀ẹ́dégbèje ọjọ́ ó lé márùndínlógójì náà ṣe ń bá a lọ, báwo ni ipò tẹ̀mí àwọn ẹni àmì òróró ṣe yí padà?

26 Àmọ́ bí ẹ̀ẹ́dégbèje ọjọ́ ó lé márùndínlógójì [1,335] náà ṣe ń bá a lọ, gbogbo èyí wá bẹ̀rẹ̀ sí yí padà. Iṣẹ́ ìwàásù wá gba iwájú, bí ó ṣe di pé a gbé àwọn ètò tí ó ṣe déédéé kalẹ̀ kí olúkúlùkù fi lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. A ṣètò àwọn ìpàdé láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ìtẹ̀jáde ti March 1, 1925 (Gẹ̀ẹ́sì), gbé àkòrí pàtàkì náà, “Ìbí Orílẹ̀-Èdè Náà” jáde, tí ó wá jẹ́ kí àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lákòókò ọdún 1914 sí 1919. Lẹ́yìn tí ọdún 1925 ré kọjá, àwọn ènìyàn mímọ́ kò tún tìtorí à ń fojú sun ọjọ́ kan pàtó, tí kò ní pẹ́ dé, sin Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìsọdimímọ́ orúkọ Jèhófà ni ó jẹ wọ́n lọ́kàn jù lọ. A tẹnu mọ́ òtítọ́ tí ó ṣe kókó yìí ju tìgbàkigbà rí lọ nínú àpilẹ̀kọ náà, “Ta Ni Yóò Bọlá fún Jèhófà?” nínú Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) January 1, 1926. Nígbà àpéjọpọ̀ ti May 1926, a mú ìwé náà Idande jáde. (Wo ojú ìwé 302.) Èyí jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀wọ́ àwọn ìwé tí a pète láti fi rọ́pò ìwé Studies in the Scriptures. Àwọn ènìyàn mímọ́ kò tún wẹ̀yìn mọ́. Ọjọ́ iwájú àti iṣẹ́ tí ń bẹ níwájú ni wọ́n fi ìdánilójú gbájú mọ́. Nítorí náà, bí a ṣe sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ipò ayọ̀ ni àwọn ènìyàn mímọ́ fi parí ẹ̀ẹ́dégbèje ọjọ́ ó lé márùndínlógójì náà.

27. Báwo ni àkópọ̀ Dáníẹ́lì orí kejìlá ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti lè dá àwọn ẹni àmì òróró Jèhófà mọ̀ dáadáa?

27 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo wọn ló forí tì í ní sáà rúgúdù yìí. Ó dájú pé ìdí nìyẹn tí áńgẹ́lì náà ti fi tẹnu mọ́ bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti máa “bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà.” Àwọn tí wọ́n forí tì í tí wọ́n sì ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà ni a bù kún gidigidi. Àkópọ̀ Dáníẹ́lì orí kejìlá mú kí èyí túbọ̀ ṣe kedere. Bí a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, a mú àwọn ẹni àmì òróró sọjí, tàbí pé a jí wọn dìde, lọ́nà tẹ̀mí. A fún wọn ní àkànṣe ìjìnlẹ̀ òye nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nípa pé a fún wọn lágbára láti lè “máa lọ káàkiri” nínú rẹ̀, àti pé, lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́, wọ́n rójútùú àwọn àdììtú àtayébáyé. Jèhófà wẹ̀ wọ́n mọ́, ó sì mú kí wọ́n máa tàn yòò nípa tẹ̀mí, gẹ́gẹ́ bí ìràwọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n mú kí ọ̀pọ̀ di ẹni tí ó wà ní ipò olódodo lójú Jèhófà Ọlọ́run.

28, 29. Kí ló yẹ kí ó jẹ́ ìpinnu wa bí “àkókò òpin” ṣe ń sún mọ́ ìparí rẹ̀?

28 Bí gbogbo àwọn àmì alásọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ṣe wà láti lè fi dá “àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ” mọ̀, àwíjàre kankan ha lè wà fún kíkùnà láti dá wọn mọ̀ kí a sì dara pọ̀ mọ́ wọn bí? Àgbàyanu ìbùkún ní ń bẹ́ níwájú fún àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró tí iye wọn ń dín kù lọ yìí láti sin Jèhófà. Gbogbo wa ní láti máa bá a lọ ní ríretí ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run. (Hábákúkù 2:3) Lọ́jọ́ tiwa yìí, Máíkẹ́lì, Ọmọ Aládé Ńlá náà, ti ń dúró ní tìtorí àwọn ènìyàn Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Láìpẹ́ sí ìsinsìnyí, yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Ọlọ́run yàn láti mú ìdájọ́ ṣẹ sórí ètò àwọn nǹkan yìí. Nígbà tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìhà wo ni àwa yóò wà?

29 Ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn yóò sinmi lórí bóyá a yàn láti gbé ìgbésí ayé ẹni tí ń pàwà títọ́ mọ́ nísinsìnyí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Láti lè fún ìpinnu wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ lókun sí i, bí “àkókò òpin” ṣe ń sún mọ́lé, ẹ jẹ́ kí a gbé ẹsẹ tí ó kẹ́yìn ìwé Dáníẹ́lì yẹ̀ wò. Bí a ó ṣe jíròrò rẹ̀ nínú orí tí ó tẹ̀ lé e yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ kí a mọ ipò tí Dáníẹ́lì wà lójú Ọlọ́run rẹ̀ àti ipò tí yóò wà lójú Rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 21 A kàn túmọ̀ rẹ̀ sí “ẹbọ” nínú Bíbélì Septuagint ti Gíríìkì.

KÍ LO LÓYE?

Ní àkókò wo ni Máíkẹ́lì “dúró,” báwo ni yóò ṣe “dìde dúró,” ìgbà wo sì ni?

Àjíǹde wo ni Dáníẹ́lì 12:2 tọ́ka sí?

Àwọn déètì wo ni ó jẹ́ àmì ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin

ìgbà mẹ́ta àti ààbọ̀ tí a mẹ́nu kàn ní Dáníẹ́lì 12:7?

àádọ́rùn-ún lé ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́ nínú Dáníẹ́lì 12:11?

ẹ̀ẹ́dégbèje ọjọ́ ó lé márùndínlógójì tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 12:12?

Báwo ni kíkíyèsí Dáníẹ́lì orí kejìlá ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti dá àwọn olùjọsìn Jèhófà tòótọ́ mọ̀?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 298]

ÌMÚKÚRÒ APÁ PÀTÀKÌ ÌGBÀ GBOGBO

Nínú ìwé Dáníẹ́lì, ẹ̀ẹ̀marùn-ún ni gbólóhùn náà, “apá pàtàkì ìgbà gbogbo,” fara hàn. Ó tọ́ka sí ẹbọ ìyìn—“èso ètè”—tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run máa ń rú sí i déédéé. (Hébérù 13:15) Àsọtẹ́lẹ̀ pé a óò mú un kúrò ni a tọ́ka sí nínú Dáníẹ́lì 8:11; 11:31, àti 12:11.

Nígbà ogun àgbáyé méjèèjì, a ṣe inúnibíni líle koko sí àwọn ènìyàn Jèhófà nínú ilẹ̀ “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù.” (Dáníẹ́lì 11:14, 15) Ìmúkúrò “apá pàtàkì ìgbà gbogbo” wáyé ní apá ìparí Ogun Àgbáyé Kìíní nígbà tí a fẹ́rẹ̀ẹ́ dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró ní àárín ọdún 1918. (Dáníẹ́lì 12:7) Bákan náà, nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà mú “apá pàtàkì ìgbà gbogbo kúrò” fún ẹ̀ẹ́dégbèjìlá ọjọ́. (Dáníẹ́lì 8:11-14; wo Orí Kẹwàá ìwé yìí.) “Àwọn apá” ìjọba Násì náà tún mú un kúrò fún àkókò tí Ìwé Mímọ́ kò sọ bí yóò ṣe gùn tó.—Dáníẹ́lì 11:31; wo Orí Kẹẹ̀ẹ́dógún ìwé yìí.

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 301]

ÀWỌN ÀKÓKÒ ALÁSỌTẸ́LẸ̀ NÍNÚ DÁNÍẸ́LÌ

Ìgbà méje (ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá ó lé October 607 ṣááju Sànmánì Tiwa sí

ogún [2,520] ọdún): October 1914 Sànmánì Tiwa

Dáníẹ́lì 4:16, 25 (A gbé Ìjọba Mèsáyà kalẹ.

Wo Orí Kẹfà ìwé yìí.)

Ìgbà mẹ́ta àti ààbọ̀ December 1914 sí June 1918

(Ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà [1,260] ọjọ́): (A dààmú àwọn Kristẹni Ẹni Àmì

Dáníẹ́lì 7:25; 12:7 Òróró. Wo Orí Kẹsàn-án ìwé yìí.)

Ẹ̀ẹ́dégbèjìlá [2,300] alẹ́ àti June 1 tàbí 15, 1938, sí

òwúrọ̀: October 8 tàbí 22, 1944

Dáníẹ́lì 8:14 (“Ogunlọ́gọ̀ ńlá” fara hàn, ó di

púpọ̀. Wo Orí Kẹwàá ìwé yìí.)

Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ (ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó dín 455 ṣááju Sànmánì Tiwa

mẹwàá [490] ọdún): sí 36 Sànmánì Tiwa

Dáníẹ́lì 9:24-27 (Díde Mèsáyà àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí

ilẹ̀ ayé. Wo Orí Kọkànlá ìwé yìí.)

Àádọ́rùn-ún lé ní ẹgbẹ̀fà January 1919 sí

[1,290] ọjọ́: September 1922

Dáníẹ́lì 12:11 (Àwọn Kristẹni Ẹni Àmì Òróró jí,

wọ́n sì tẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí.)

Ẹ̀ẹ́dégbèje ó lé márùndínlógójì September 1922 sí May 1926

[1,335] ọjọ́: (Awọn Kristẹni Àmì Òróró dé ipò

Dáníẹ́lì 12:12 ayọ̀.)

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 287]

A fi àìtọ́ ju àwọn sàràkí-sàràkí lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba àpapọ̀ ní ìlú Atlanta, Georgia, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Láti apá òsì sí ọ̀tún: (ní ìjókòó) A. H. Macmillan, J. F. Rutherford, W. E. Van Amburgh; (ní ìdúró) G. H. Fisher, R. J. Martin, G. DeCecca, F. H. Robison, àti C. J. Woodworth

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 299]

A ṣe àwọn àpéjọpọ̀ pàtàkì pàtàkì ní ìlú Cedar Point, Ohio, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, lọ́dún 1919 (lókè) àti 1922 (nísàlẹ̀)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 302]