Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta ni Yóò Ṣàkóso Ayé?

Ta ni Yóò Ṣàkóso Ayé?

Orí Kẹsàn-án

Ta ni Yóò Ṣàkóso Ayé?

1-3. Ṣàpèjúwe àlá àti àwọn ìran tí Dáníẹ́lì rí ní ọdún kìíní ìṣàkóso Bẹliṣásárì.

ÀSỌTẸ́LẸ̀ Dáníẹ́lì tí ó ń gba àfiyèsí ẹni wá dá wa padà sí ọdún kìíní Bẹliṣásárì ọba Bábílónì. Ó ti pẹ́ tí Dáníẹ́lì ti jẹ́ ìgbèkùn ní Bábílónì, ṣùgbọ́n ìwà títọ́ rẹ̀ sí Jèhófà kò fìgbà kankan yingin. Wòlíì olùṣòtítọ́ náà, tí ọjọ́ orí rẹ̀ ti lé ní àádọ́rin ọdún báyìí, “lá àlá, ó sì rí àwọn ìran orí rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀.” Áà, jìnnìjìnnì tí àwọn ìran náà kó bá a mà pọ̀ o!—Dáníẹ́lì 7:1, 15.

2 Dáníẹ́lì kígbe pé: “Sì wò ó! ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run ń ru alagbalúgbú òkun sókè. Ẹranko mẹ́rin tí ó tóbi fàkìàfakia sì ń jáde bọ̀ láti inú òkun, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yàtọ̀ síra.” Àwọn àràmàǹdà ẹranko mà rèé o! Àkọ́kọ́ jẹ́ kìnnìún tí ó níyẹ̀ẹ́ lápá, ìkejì sì dà bí béárì. Bẹ́ẹ̀ ni àmọ̀tẹ́kùn tí ó ní ìyẹ́ apá mẹ́rin àti orí mẹ́rin tún jáde wá! Ẹranko kẹrin tí ó lágbára lọ́nà kíkàmàmà ní eyín irin ńláńlá àti ìwo mẹ́wàá. Ní àárín ìwo mẹ́wàá tí ó ní ni ìwo kan “tí ó kéré” ti jáde wá, ó ní “ojú bí ojú ènìyàn” àti “ẹnu tí ń sọ àwọn nǹkan kàbìtìkàbìtì.”—Dáníẹ́lì 7:2-8.

3 Lẹ́yìn èyí, Dáníẹ́lì wá rí ọ̀run nínú ìran. Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé gúnwà lọ́nà ológo gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ ní Kóòtù ọ̀run. “Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì ń dúró níwájú rẹ̀ gangan.” Bí ó ṣe dá àwọn ẹranko náà lẹ́bi, ó gba ìṣàkóso kúrò lọ́wọ́ wọn, ó sì pa ẹranko kẹrin run. Agbára ìṣàkóso fún àkókò tí ó lọ kánrin, lórí “àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè,” ni a gbé wọ “ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn.”—Dáníẹ́lì 7:9-14.

4. (a) Ta ni Dáníẹ́lì yíjú sí fún ìsọfúnni tí ó ṣeé fọkàn tẹ̀? (b) Èé ṣe tí ohun tí Dáníẹ́lì rí tí ó sì gbọ́ lóru yẹn fi ṣe pàtàkì fún wa?

4 Dáníẹ́lì sọ pé: “Ní ti èmi, wàhálà-ọkàn bá ẹ̀mí mi nínú mi ní tìtorí èyí, ìran orí mi sì bẹ̀rẹ̀ sí kó jìnnìjìnnì bá mi.” Nítorí náà, ó béèrè fún “ìsọfúnni tí ó ṣeé fọkàn tẹ̀ lórí gbogbo èyí” lọ́wọ́ áńgẹ́lì kan. Lóòótọ́, áńgẹ́lì náà sọ ohun tí “ìtumọ̀ àwọn ọ̀ràn náà gan-an” jẹ́ fún un. (Dáníẹ́lì 7:15-28) Ohun tí Dáníẹ́lì rí tí ó sì gbọ́ ní òru yẹn fà wá lọ́kàn mọ́ra gidigidi, nítorí pé ó sọ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú yóò ṣe ṣẹlẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ títí kan ìgbà tiwa, nígbà tí a gbé agbára ìṣàkóso lórí “gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè,” fún “ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn.” Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, àwa pẹ̀lú lè lóye ìtumọ̀ àwọn ìran alásọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn. *

ẸRANKO MẸ́RIN JÁDE WÁ LÁTI INÚ ÒKUN

5. Kí ni òkun tí ẹ̀fúùfù ń gbá yẹn ṣàpẹẹrẹ?

5 Dáníẹ́lì sọ pé: “Ẹranko mẹ́rin tí ó tóbi fàkìàfakia sì ń jáde bọ̀ láti inú òkun.” (Dáníẹ́lì 7:3) Kí ni òkun tí ẹ̀fúùfù ń gbá náà ṣàpẹẹrẹ? Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Jòhánù rí i tí ẹranko ẹhànnà olórí méje kan jáde wá láti inú “òkun.” Òkun yẹn dúró fún “àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n”—àpapọ̀ ọ̀pọ̀ yanturu aráyé, tí wọ́n kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Nígbà náà, òkun jẹ́ àpẹẹrẹ tí ó ṣe wẹ́kú fún àwùjọ aráyé tí a sọ di àjèjì sí Ọlọ́run.—Ìṣípayá 13:1, 2; 17:15; Aísáyà 57:20.

6. Kí ni ẹranko mẹ́rin náà dúró fún?

6 Áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ pé: “Ní ti àwọn ẹranko títóbi fàkìàfakia yìí, nítorí pé mẹ́rin ni wọ́n, ọba mẹ́rin ni yóò dìde ní ilẹ̀ ayé.” (Dáníẹ́lì 7:17) Ní kedere, áńgẹ́lì náà sọ pé àwọn ẹranko mẹ́rin tí Dáníẹ́lì rí jẹ́ “ọba mẹ́rin.” Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ẹranko wọ̀nyí dúró fún àwọn agbára ayé. Ṣùgbọ́n àwọn wo ni?

7. (a) Kí ni àwọn alálàyé lórí Bíbélì kan sọ nípa ìran ẹranko mẹ́rin inú àlá Dáníẹ́lì àti àlá tí Nebukadinésárì Ọba lá nípa ère arabarìbì kan? (b) Kí ni ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú apá onírin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ara ère náà dúró fún?

7 Àwọn alálàyé lórí Bíbélì sábà máa ń so ìran ẹranko mẹ́rin inú àlá Dáníẹ́lì pọ̀ mọ́ àlá ère arabarìbì ti Nebukadinésárì. Bí àpẹẹrẹ, ìwé The Expositor’s Bible Commentary sọ pé: “Orí keje [ìwé Dáníẹ́lì] jọ orí kejì.” Ìwé The Wycliffe Bible Commentary sọ pé: “A gbà ní gbogbo gbòò pé bákan náà ni ìtòtẹ̀léra ìṣàkóso àwọn Kèfèrí mẹ́rin . . . tí ó wà níhìn-ín [ní Dáníẹ́lì orí keje] jẹ́ pẹ̀lú èyí tí a gbé yẹ̀ wò nínú [Dáníẹ́lì] orí kejì.” Agbára ayé mẹ́rin tí a fi àwọn oríṣi irin mẹ́rin inú àlá Nebukadinésárì ṣàpẹẹrẹ ni Ilẹ̀ Ọba Bábílónì (orí wúrà), Mídíà òun Páṣíà (igẹ̀ àti apá fàdákà), Gíríìsì (ikùn àti itan bàbà), àti Ilẹ̀ Ọba Róòmù (ẹsẹ̀ irin). * (Dáníẹ́lì 2:32, 33) Ẹ jẹ́ kí a wo bí àwọn ìjọba wọ̀nyí ṣe bá àwọn ẹranko fàkìàfakia mẹ́rin tí Dáníẹ́lì rí mu.

Ó RORÒ BÍI KÌNNÌÚN, Ó Ń JÁ ṢÒÒRÒṢÒ BÍ IDÌ

8. (a) Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe ẹranko àkọ́kọ́? (b) Ilẹ̀ ọba wo ni ẹranko àkọ́kọ́ ṣàpẹẹrẹ, báwo ni ó sì ṣe hùwà bí kìnnìún?

8 Áà, àwọn abàmì ẹranko ni Dáníẹ́lì rí! Nígbà tí ó ń ṣàpèjúwe ọ̀kan ó ní: “Èyí àkọ́kọ́ dà bí kìnnìún, ó sì ní ìyẹ́ apá idì. Mo ń wò ó títí a fi fa ìyẹ́ apá rẹ̀ tu, a sì gbé e sókè lórí ilẹ̀ ayé, a sì mú kí ó dìde dúró lórí ẹsẹ̀ méjì bí ènìyàn, a sì fún un ní ọkàn-àyà ènìyàn.” (Dáníẹ́lì 7:4) Ẹranko yìí ṣàpẹẹrẹ ìṣàkóso kan náà tí orí wúrà ère arabarìbì náà dúró fún, Agbára Ayé Bábílónì (ọdún 607 sí 539 ṣááju Sànmánì Tiwa). Bíi “kìnnìún,” ẹran aṣọdẹ, bẹ́ẹ̀ ni Bábílónì ń jẹ àwọn orílẹ̀-èdè lọ ràì, títí kan àwọn ènìyàn Ọlọ́run. (Jeremáyà 4:5-7; 50:17) Jíjá ni “kìnnìún” yìí ń já ṣòòròṣò, bí ó ṣe ń fi ìwàǹwára ṣẹ́gun lọ, àfi bí pé ó ní ìyẹ́ apá idì.—Ìdárò 4:19; Hábákúkù 1:6-8.

9. Àwọn àyípadà wo ni ó bá ẹranko tí ó dà bí kìnnìún yìí, báwo sì ní wọ́n ṣe nípa lórí rẹ̀?

9 Nígbà tí ó ṣe, a bá “fa” àwọn ìyẹ́ apá kìnnìún abàmì yìí “tu.” Ní apá ìgbẹ̀yìn ìṣàkóso Bẹliṣásárì Ọba, Bábílónì pàdánù agbára ìyára kánkán ṣẹ́gun rẹ̀ àti agbára àjùlọ bí kìnnìún tí ó ní lórí àwọn orílẹ̀-èdè. Gbogbo eré sísá rẹ̀ kò ju tí ènìyàn ẹlẹ́sẹ̀ méjì péré lọ. Ní gbígbà tí ó gba “ọkàn-àyà ènìyàn,” ó di aláìlágbára. Bí Bábílónì kò ti ní “ọkàn-àyà” tí ó “dà bí ọkàn-àyà kìnnìún,” kò lè ṣe bí ọba “láàárín àwọn ẹranko igbó” mọ́. (Fi wé 2 Sámúẹ́lì 17:10; Míkà 5:8.) Bí ẹranko títóbi fàkìàfakia mìíràn ṣe ṣẹ́gun rẹ̀ nìyẹn.

Ó Ń JẸ ÌJẸWỌ̀MÙ BÍ BÉÁRÌ

10. Ìlà àwọn ọba wo ni “béárì” náà ṣàpẹẹrẹ?

10 Dáníẹ́lì sọ pé: “Sì wò ó! ẹranko mìíràn, èkejì, ó dà bí béárì. A sì gbé e sókè ní ìhà kan, egungun ìhà mẹ́ta sì wà ní ẹnu rẹ̀ láàárín eyín rẹ̀; ohun tí wọn sì ń sọ fún un nìyí, ‘Dìde, jẹ ẹran púpọ̀.’” (Dáníẹ́lì 7:5) Ọba tí a fi “béárì” ṣàpẹẹrẹ yìí kan náà ni a fi igẹ̀ àti apá ère ńlá yẹn ṣàpẹẹrẹ—ìlà àwọn ọba Mídíà òun Páṣíà (ọdún 539 sí 331 ṣááju Sànmánì Tiwa), ó bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Dáríúsì ará Mídíà àti Kírúsì Ńlá, ó sì parí sí ọ̀dọ̀ Dáríúsì Kẹta.

11. Kí ni gbígbé tí a gbé béárì ìṣàpẹẹrẹ náà sókè ní ìhà kan àti níní tí ó ní egungun ìhà mẹ́ta ní ẹnu rẹ̀ ṣàpẹẹrẹ?

11 A gbé “béárì” ìṣàpẹẹrẹ náà ‘sókè ní ìhà kan’ bóyá kí ó bàa lè wà ní sẹpẹ́ fún àtikọlu àwọn orílẹ̀-èdè, kí ó ṣẹ́gun wọn, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ máa bá a lọ gẹ́gẹ́ bí agbára ayé. Tàbí kí ipò tí ó wà yẹn jẹ́ ọ̀nà kan láti gbà fi hàn pé àwọn ọba láti ìlà ilẹ̀ Páṣíà yóò mókè lórí Dáríúsì, ọba kan ṣoṣo tí ó jẹ́ ará Mídíà. Egungun ìhà mẹ́ta tí ó wà lẹ́nu béárì náà lè tọ́ka sí apá ibi mẹ́ta tí ó gbé ìṣẹ́gun rẹ̀ gbà lọ. “Béárì” tí í ṣe Mídíà òun Páṣíà lọ sí àríwá, ó sì gba Bábílónì ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa. Lẹ́yìn náà, ó lọ síhà ìwọ̀-oòrùn, ó bá ọ̀nà Éṣíà Kékeré wọ Tírésì. Níkẹyìn, “béárì” náà lọ síhà gúúsù láti lọ ṣẹ́gun Íjíbítì. Níwọ̀n bí iye náà, ẹẹ́ta, ti máa ń dúró fún ìgbóná janjan, egungun ìhà mẹ́ta náà tún lè jẹ́ ìtẹnumọ́ ní ti bí béárì ìṣàpẹẹrẹ náà ṣe jẹ́ oníwọra tó lẹ́nu ìṣẹ́gun rẹ̀.

12. Kí ní jẹyọ láti inú bí béárì ìṣàpẹẹrẹ náà ṣe ṣègbọràn sí àṣẹ náà pé: “Dìde, jẹ ẹran púpọ̀”?

12 “Béárì” náà ṣe ohun tí a sọ pé: “Dìde, jẹ ẹran púpọ̀,” nípa kíkọlu àwọn orílẹ̀-èdè. Nípa jíjẹ tí Mídíà òun Páṣíà jẹ Bábílónì ráúráú ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run, ó di èyí tí ó wà ní ipò láti lè ṣe iṣẹ́ takuntakun fún àwọn ènìyàn Jèhófà. Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́! (Wo “Ọba Tí Kì Í Fi Nǹkan Nini Lára,” ní ojú ìwé 149.) Nípasẹ̀ Kírúsì Ńlá, Dáríúsì Kìíní (Dáríúsì Ńlá), àti Atasásítà Kìíní, Mídíà òun Páṣíà dá àwọn Júù òǹdè Bábílónì sílẹ̀, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà àti láti tún àwọn odi Jerúsálẹ́mù kọ́. Nígbà tí ó ṣe, Mídíà òun Páṣíà wá di èyí tí ó ń ṣàkóso lórí àgbègbè abẹ́ àṣẹ tí ó jẹ́ mẹ́tà-dín-láàádóje, Ahasuwérúsì (Sásítà Kìíní) tí í ṣe ọkọ Ẹ́sítérì Ayaba, jẹ́ “ọba láti Íńdíà títí dé Etiópíà.” (Ẹ́sítérì 1:1) Àmọ́ ṣá, ẹranko mìíràn fẹ́rẹ̀ẹ́ dìde láìpẹ́.

Ó Ń YÁRA KÁNKÁN BÍ ÀMỌ̀TẸ́KÙN TÍ Ó NÍYẸ̀Ẹ́ LÁPÁ!

13. (a) Kí ni ẹranko kẹta ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí ni a lè sọ nípa ìyára kankan ẹranko kẹta àti ilẹ̀ àkóso tí ó wà lábẹ́ rẹ̀?

13 Ẹranko kẹta “dà bí àmọ̀tẹ́kùn, ṣùgbọ́n, ó ní ìyẹ́ apá mẹ́rin ti ẹ̀dá tí ń fò ní ẹ̀yìn rẹ̀. Ẹranko náà sì ní orí mẹ́rin, agbára ìṣàkóso ni a sì fi fún un ní ti gidi.” (Dáníẹ́lì 7:6) Gẹ́gẹ́ bí ìkejì rẹ̀—ikùn àti itan bàbà ti ère inú àlá Nebukadinésárì—ṣe jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni àmọ̀tẹ́kùn tí ó ní orí mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin yìí ṣe dúró fún ìlà àwọn alákòóso tí ó jẹ́ ará Makedóníà, tàbí ti Gíríìsì, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Alẹkisáńdà Ńlá. Gan-an bí àmọ̀tẹ́kùn ṣe ń bẹ́ gìjà tí ó sì ń yára kánkán, bẹ́ẹ̀ ni Alẹkisáńdà ṣe la Éṣíà Kékeré kọjá síhà gúúsù tí ó sì wọ Íjíbítì, tí ó sì tún kọjá lọ síhà ìwọ̀-oòrùn ààlà Íńdíà. (Fi wé Hábákúkù 1:8.) Ilẹ̀ àkóso rẹ̀ tóbi ju ti “béárì” náà lọ, nítorí ó mú Makedóníà, Gíríìsì, àti Ilẹ̀ Ọba Páṣíà mọ́ra.—Wo “Ọ̀dọ́ Ọba Kan Ṣẹ́gun Ayé,” ní ojú ìwé 153.

14. Báwo ni “àmọ̀tẹ́kùn” náà ṣe di olórí mẹ́rin?

14 “Àmọ̀tẹ́kùn” náà di olórí mẹ́rin lẹ́yìn ikú Alẹkisáńdà ní ọdún 323 ṣááju Sànmánì Tiwa. Mẹ́rin lára àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ni wọ́n rọ́pò rẹ̀ ní ìhà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ilẹ̀ àkóso rẹ̀. Sẹ̀lẹ́úkọ́sì fọwọ́ mú Mesopotámíà àti Síríà. Pẹ́tólẹ́mì ń bójú tó Íjíbítì àti Palẹ́sínì. Lisimákù ń ṣàkóso Éṣíà Kékeré àti Tírésì, Kasáńdà sì gba Makedóníà àti Gíríìsì. (Wo “A Pín Ìjọba Gbígbòòrò Kan,” ní ojú ìwé 162.) Lẹ́yìn náà, ewu mìíràn yọjú.

ẸRANKO BÍBANILẸ́RÙ KAN TÍ Ó DÁ YÀTỌ̀

15. (a) Ṣàpèjúwe ẹranko kẹrin. (b) Kí ni ẹranko kẹrin ṣàpẹẹrẹ, báwo ni ó sì ṣe fọ́ ohun gbogbo tí ó bá pàdé túútúú, tí ó sì jẹ wọ́n ní àjẹrun?

15 Dáníẹ́lì ṣàpèjúwe ẹranko kẹrin pé ó jẹ́ èyí tí ó “bani lẹ́rù, tí ń jáni láyà, tí ó sì lágbára lọ́nà kíkàmàmà.” Ó ń bá a lọ pé: “Ó sì ní eyín irin, wọ́n tóbi. Ó ń jẹ ní àjẹrun, ó sì ń fọ́ túútúú, ohun tí ó sì ṣẹ́ kù ni ó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀. Ó jẹ́ ohun kan tí ó yàtọ̀ sí gbogbo ẹranko yòókù tí ó wà ṣáájú rẹ̀, ó sì ní ìwo mẹ́wàá.” (Dáníẹ́lì 7:7) Ẹranko tí ó bani lẹ́rù náà bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọba ìṣèlú àti ti ológun ní ilẹ̀ Róòmù. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó gba àkóso àwọn ìhà Hélénì mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì pín sí, nígbà tí ó sì fi di ọdún 30 ṣááju Sànmánì Tiwa, Róòmù ti yọjú gẹ́gẹ́ bí agbára ayé tí ó bọ́ sójú ọpọ́n nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Bí Ilẹ̀ Ọba Róòmù ṣe ń fi agbára ológun tẹ ohun gbogbo tí ó bá bá pàdé lórí ba, ó gbilẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ dé àgbègbè tí ó nasẹ̀ láti Àwọn Erékùṣù Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá ìsàlẹ̀ sí ibi tí ó pọ̀ jù lọ nínú ilẹ̀ Yúróòpù, títí yí ká Mẹditaréníà, ó sì ré kọjá Bábílónì lọ sí Ìyawọlẹ̀ Omi Páṣíà.

16. Ìsọfúnni wo ni áńgẹ́lì náà sọ nípa ẹranko kẹrin?

16 Bí Dáníẹ́lì ṣe nífẹ̀ẹ́ sí mímọ̀ dájú nípa ẹranko “tí ó bani lẹ́rù lọ́nà àrà ọ̀tọ̀” náà, ó tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ bí áńgẹ́lì náà ṣe ń ṣàlàyé pé: “Ní ti ìwo mẹ́wàá [tí ó ní], láti inú ìjọba yẹn, ọba mẹ́wàá ni yóò dìde; òmíràn yóò sì tún dìde lẹ́yìn wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì yàtọ̀ sí àwọn ti àkọ́kọ́, yóò sì tẹ́ ọba mẹ́ta lógo.” (Dáníẹ́lì 7:19, 20, 24) Kí ni àwọn “ìwo mẹ́wàá” tàbí “ọba mẹ́wàá” yìí jẹ́?

17. Kí ni “ìwo mẹ́wàá” ẹranko kẹrin ṣàpẹẹrẹ?

17 Bí ọ̀làjú ilẹ̀ Róòmù ṣe ń tẹ̀ síwájú sí i, tí gbígbé tí àwọn aláṣẹ ìlú ń gbé ìgbé ayé ìwà ìbàjẹ́ sì túbọ̀ sọ ọ́ dìbàjẹ́, bẹ́ẹ̀ ni agbára ológun tí ó ní bẹ̀rẹ̀ sí lọ sílẹ̀. Nígbà tí ó ṣe, ó wá hàn kedere pé agbára ìjagun Róòmù ti relẹ̀. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ilẹ̀ ọba títóbi náà pín sí ìjọba púpọ̀. Níwọ̀n bí Bíbélì ti sábà máa ń lo iye náà, ẹẹ́wàá, láti dúró fún ìpé pérépéré, “ìwo mẹ́wàá” ẹranko kẹrin ṣàpẹẹrẹ gbogbo àwọn ìjọba tí ó jẹyọ láti inú fífọ́ tí Róòmù fọ́ sí wẹ́wẹ́.—Fi wé Diutarónómì 4:13; Lúùkù 15:8; 19:13, 16, 17.

18. Báwo ni Róòmù ṣe ń bá a lọ láti lo àṣẹ lórí ilẹ̀ Yúróòpù fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn tí a mú olú ọba tí ó kẹ́yìn níbẹ̀ kúrò?

18 Ṣùgbọ́n, mímú tí a mú olú ọba tí ó jẹ kẹ́yìn ní Róòmù kúrò ní ọdún 476 Sànmánì Tiwa kò fòpin sí Agbára Ayé Róòmù. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rúndún ni póòpù ní Róòmù fi ń bá a lọ láti lo àṣẹ ìṣèlú, àti ti ìsìn ní pàtàkì, lórí ilẹ̀ Yúróòpù. Ètò òṣìṣẹ́-wà-lóòrùn ni ó gbé kalẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn olùgbé ilẹ̀ Yúróòpù ní olúwa tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún, olúwa yẹn sì wà lábẹ́ ọba kan. Gbogbo ọba sì gbà pé àwọn wà lábẹ́ àṣẹ póòpù. Báyìí ni Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́, tí póòpù jẹ́ olórí rẹ̀, ṣe darí àlámọ̀rí ayé jálẹ̀ sáà gígùn yẹn tí a ń pè ní Sànmánì Ojú Dúdú.

19. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn kan ṣe wí, báwo ni Róòmù ṣe rí tí a bá fi wéra pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ṣáájú rẹ̀?

19 Ta ní lè já òtítọ́ yẹn ní koro pé ẹranko kẹrin “yàtọ̀ sí gbogbo ìjọba yòókù”? (Dáníẹ́lì 7:7, 19, 23) Ní ti èyí, òpìtàn H. G. Wells kọ̀wé pé: “Agbára Róòmù tuntun yìí . . . jẹ́ èyí tí ó yàtọ̀ lọ́nà púpọ̀ sí èyíkéyìí nínú àwọn ilẹ̀ ọba ńláńlá tí ó tíì wà lórí ayé ọ̀làjú títí di ìsinsìnyí. . . . [Ó] fẹ́rẹ̀ẹ́ kó gbogbo Gíríìkì inú ayé mọ́ra tán, àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì jẹ́ ti ìran Hámù àti ti Ṣémù látòkè délẹ̀ bí àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ṣáájú rẹ̀ . . . Títí di báyìí, ìlànà tuntun ni ó jẹ́ nínú ìtàn . . . Ilẹ̀ Ọba Róòmù jẹ́ ìdàgbàsókè kan tó ṣẹlẹ̀ ní ìjafùú, ohun tuntun tí a kò wéwèé rẹ̀ tẹ́lẹ̀; ńṣe ni àwọn ènìyàn Róòmù kàn rí i pé àwọn ń ṣakitiyan láti ṣàkóso lọ́nà gbígbòòrò.” Síbẹ̀, ẹranko kẹrin yìí ṣì máa ní èèhù sí i.

ÌWO KÉKERÉ KAN GORÍ ÌTẸ́

20. Kí ni áńgẹ́lì náà sọ nípa híhù tí ìwo kékeré kan hù lórí ẹranko kẹrin?

20 Dáníẹ́lì sọ pé: “Mo ń ronú nípa àwọn ìwo náà, sì wò ó! ìwo mìíràn, ọ̀kan tí ó kéré, jáde wá láàárín wọn, mẹ́ta lára àwọn ìwo àkọ́kọ́ ni a sì fà tu níwájú rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 7:8) Áńgẹ́lì náà sọ fún Dáníẹ́lì nípa ìwo tí ó hù yìí pé: “Òmíràn yóò . . . dìde lẹ́yìn wọn [ọba mẹ́wàá náà], òun fúnra rẹ̀ yóò sì yàtọ̀ sí àwọn ti àkọ́kọ́, yóò sì tẹ́ ọba mẹ́ta lógo.” (Dáníẹ́lì 7:24) Ta ni ọba yìí, ìgbà wo ni ó díde, ọba mẹ́ta wo sì ni ó tẹ́ lógo?

21. Báwo ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe wá di ìwo kékeré ìṣàpẹẹrẹ tí ẹranko kẹrin ní?

21 Gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí yẹ̀ wò. Ní ọdún 55 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ọ̀gágun Júlíọ́sì Késárì ará Róòmù gbé ogun ja ilẹ̀ Britannia ṣùgbọ́n kò ṣeé ṣe fún un láti máa wà níbẹ̀ títí lọ. Ní ọdún 43 Sànmánì Tiwa, Olú Ọba Kíláúdíù bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ́gun tí ó túbọ̀ wà pẹ́ títí lórí gúúsù ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Lẹ́yìn náà, ní ọdún 122 Sànmánì Tiwa, Olú Ọba Hádíríánì bẹ̀rẹ̀ sí mọ odi kan láti Odò Táìnì títí dé Ìwọdò Solway tí ó sàmì sí ààlà Ilẹ̀ Ọba Róòmù níhà àríwá. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún karùn-ún, ọ̀wọ́ ẹgbẹ́ ogun Róòmù kúrò ní erékùṣù náà. Òpìtàn kan ṣàlàyé pé: “Ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jẹ́ ìjọba kan tí a kò fi bẹ́ẹ̀ kà sí. Ọrọ̀ rẹ̀ kéré sí ti ilẹ̀ Netherlands. Àwọn ènìyàn rẹ̀ kò pọ̀ tó ti ilẹ̀ Faransé. Agbo ọmọ ogun rẹ̀ (títí kan àwọn ọmọ ogun ojú omi) kò lágbára tó ti ilẹ̀ Sípéènì.” Dájúdájú, nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tí ó jẹ́ ìwo kékeré ìṣàpẹẹrẹ lára ẹranko kẹrin, jẹ́ ìjọba tí kò jámọ́ nǹkan kan. Ṣùgbọ́n, àyípadà fẹ́rẹ̀ẹ́ bá a láìpẹ́.

22. (a) Àwọn ìwo mẹ́ta mìíràn wo lórí ẹranko kẹrin ni ìwo “tí ó kéré” náà borí? (b) Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá di kí ni?

22 Lọ́dún 1588, Fílípì Kejì ti ilẹ̀ Sípéènì kó Ọ̀wọ́ Ọkọ̀ Ogun Ojú Omi ti ilẹ̀ Sípéènì lọ láti gbéjà ko ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun wọ̀nyí, tí iye wọn jẹ́ àádóje, kó èyí tí ó ju ẹgbàá méjìlá [24,000] ènìyàn gba ojú òkun tí ó wà láàárín Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Faransé wá, àmọ́, ńṣe ni àwọn ọmọ ogun ojú omi ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣẹ́gun wọn, wọ́n sì tún kàgbákò afẹ́fẹ́ àti ìjì líle tí ó rọ́ lù wọ́n láti inú òkun Àtìláńtíìkì. Òpìtàn kan sọ pé ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni “ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti gborí mọ́ ilẹ̀ Sípéènì lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá ní ti ọmọ ogun ojú omi.” Ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, ilẹ̀ Netherlands ni ó ní ọkọ̀ òkun àwọn oníṣòwò tí ó pọ̀ jù lọ. Ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí àwọn ilẹ̀ tí Gẹ̀ẹ́sì ń ṣàkóso lókè òkun ti ń pọ̀ sí i, ó borí ilẹ̀ Netherlands. Ní ọ̀rúndún kejìdínlógún, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ti Faransé bá ara wọn jà ní ilẹ̀ Àríwá Amẹ́ríkà àti ní Íńdíà, èyí mú kí wọ́n ṣe Àdéhùn ti ìlú Paris ní ọdún 1763. Òǹkọ̀wé náà, William B. Willcox, sọ pé àdéhùn yìí “gbà pé, nínú agbo àwọn ilẹ̀ Yúróòpù tí ó lágbára lórí àwọn ilẹ̀ mìíràn tí kì í ṣe ti Yúróòpù, ipò tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wà báyìí ló gba iwájú.” Ẹ̀rí pé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ̀gá wá fìdí múlẹ̀ nígbà tí ó ṣẹ́gun Napoléon ti ilẹ̀ Faransé yán-ányán-án lọ́dún 1815 Sànmánì Tiwa. Nípa báyìí, “ọba mẹ́ta” tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá ‘tẹ́ lógo’ ni ilẹ̀ Sípéènì, Netherlands, àti Faransé. (Dáníẹ́lì 7:24) Nípa bẹ́ẹ̀, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá yọ jáde gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ tí ó lágbára jù lọ lágbàáyé ní ti ọ̀ràn gbígbé òkèèrè ṣàkóso àti ti ìṣòwò. Bẹ́ẹ̀ ni o, ìwo “tí ó kéré” náà gbilẹ̀ títí, ó di agbára ayé!

23. Ọ̀nà wo ni ìwo kékeré ìṣàpẹẹrẹ náà gbà “jẹ gbogbo ilẹ̀ ayé ní àjẹrun”?

23 Áńgẹ́lì náà sọ fún Dáníẹ́lì pé ẹranko kẹrin, tàbí ìjọba kẹrin yóò “jẹ gbogbo ilẹ̀ ayé ní àjẹrun.” (Dáníẹ́lì 7:23) Òótọ́ sì ni ìyẹn já sí ní ti ọ̀ràn ìgbèríko Róòmù kan tí a mọ̀ sí ilẹ̀ Britannia nígbà kan rí. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó di Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì, ó sì “jẹ gbogbo ilẹ̀ ayé ní àjẹrun.” Nígbà kan rí, ìdá mẹ́rin ojú ilẹ̀ ayé àti ìdá mẹ́rin àwọn olùgbé inú ayé ni ó jẹ́ ti ilẹ̀ ọba yẹn.

24. Kí ni òpìtàn kan sọ nípa yíyàtọ̀ tí Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì yàtọ̀?

24 Bí Ilẹ̀ Ọba Róòmù ṣe yàtọ̀ sí àwọn agbára ayé yòókù tí ó wà ṣáájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ọba tí ìwo “tí ó kéré” náà ṣàpẹẹrẹ yóò ṣe “yàtọ̀ sí àwọn ti àkọ́kọ́.” (Dáníẹ́lì 7:24) Òpìtàn náà, H. G. Wells, sọ nípa Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì pé: “Irú rẹ̀ kò sí nígbà kankan rí. Ohun àkọ́kọ́, tí ó sì ṣe pàtàkì jù lọ nínú ilẹ̀ ọba náà látòkè délẹ̀ ni pé ó ní ‘orílẹ̀-èdè olómìnira tí ó ní ọba aládé’ gẹ́gẹ́ bí olórí Àpapọ̀ Àwọn Ìjọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì . . . Kò sí ilé iṣẹ́ ìjọba kankan tàbí ẹnikẹ́ni tí ó tí ì lóye Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì látòkè délẹ̀ rí. Àmúlùmálà ni, láti inú ìjọba tuntun àti ti àtijọ́, tí ó yàtọ̀ pátápátá sí èyíkéyìí nínú ilẹ̀ ọba kankan tí ó tíì wà rí.”

25. (a) Nínú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i níkẹyìn, kí ní para pọ̀ di ìwo kékeré ìṣàpẹẹrẹ náà? (b) Ní èrò wo ni ìwo “tí ó kéré” náà fi ní “àwọn ojú bí ojú ènìyàn” àti “ẹnu tí ń sọ àwọn nǹkan kàbìtìkàbìtì”?

25 Ohun tí ìwo “tí ó kéré” náà jẹ́ ju kìkì Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì lọ. Lọ́dún 1783, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gbà kí àwọn ilẹ̀ mẹ́tàlá ní Amẹ́ríkà, tí òun ń ṣàkóso láti òkèèrè, di òmìnira. Nígbà tí ó yá, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà di onígbèjà ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó sì tipasẹ̀ Ogun Àgbáyé Kejì di orílẹ̀-èdè tí ó mókè jù lọ ní àgbáyé. Àjọṣe tí ó lágbára ṣì wà láàárín òun àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì síbẹ̀. Agbára ayé aláwẹ́ méjì ti Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tí ó tibẹ̀ jẹyọ ni ó pa pọ̀ jẹ́ ‘ìwo tí ó ní ojú’ náà. Ní tòótọ́, agbára ayé yẹn mà lákiyèsí o, ó sì gbọ́n féfé! Ó “ń sọ àwọn nǹkan kàbìtìkàbìtì,” ó ń yan ìlànà ìgbàṣe-nǹkan lé ọ̀pọ̀ jù lọ nínú ayé lọ́wọ́, ó sì ń ṣe bí agbẹnusọ tàbí “wòlíì èké” fún un.—Dáníẹ́lì 7:8, 11, 20; Ìṣípayá 16:13; 19:20.

ÌWO KÉKERÉ NÁÀ TAKO ỌLỌ́RUN ÀTI ÀWỌN ẸNI MÍMỌ́ RẸ̀

26. Kí ni áńgẹ́lì náà sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣesí ìwo ìṣàpẹẹrẹ náà sí Jèhófà àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?

26 Dáníẹ́lì ń bá a lọ láti ṣàpèjúwe ìran tí ó rí pé: “Mo ń wò ó nígbà tí ìwo yẹn gan-an bá àwọn ẹni mímọ́ ja ogun, ó sì ń borí wọn.” (Dáníẹ́lì 7:21) Áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ ní ti “ìwo” tàbí ọba yìí pé: “Àní yóò . . . sọ ọ̀rọ̀ lòdì sí Ẹni Gíga Jù Lọ, yóò sì máa bá a lọ ní fífòòró àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ. Yóò sì pète-pèrò láti yí àwọn àkókò àti òfin padà, a ó sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́ fún àkókò kan, àti àwọn àkókò àti ààbọ̀ àkókò.” (Dáníẹ́lì 7:25) Báwo ni apá àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ní ìmúṣẹ, ìgbà wo sì ni?

27. (a) Àwọn wo ni “àwọn ẹni mímọ́” tí ìwo “tí ó kéré” náà ṣe inúnibíni sí? (b) Báwo ni ìwo ìṣàpẹẹrẹ náà ṣe pète “láti yí àwọn àkókò àti òfin padà”?

27 Àwọn ẹni àmì òróró, ọmọlẹ́yìn Jésù lórí ilẹ̀ ayé ni “àwọn ẹni mímọ́” tí ìwo “tí ó kéré” yìí—Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà—ṣe inúnibíni sí. (Róòmù 1:7; 1 Pétérù 2:9) Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí ń ṣe kìlọ̀kìlọ̀ fáráyé gbọ́ pé ọdún 1914 ni “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” yóò pé. (Lúùkù 21:24) Bí ogun ṣe bẹ́ sílẹ̀ ní ọdún yẹn, ó wá hàn gbangba pé ìwo “tí ó kéré” náà kọ ìkìlọ̀ yìí sílẹ̀, nítorí pé, ńṣe ló tẹra mọ́ fífòòró àwọn ẹni àmì òróró, “àwọn ẹni mímọ́.” Kódà, Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tako sísapá tí wọ́n ń sapá láti ṣe ohun tí Jèhófà béèrè (tàbí, “òfin” rẹ̀) pé kí àwọn ẹlẹ́rìí òun wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí kárí ayé. (Mátíù 24:14) Nípa báyìí, ìwo “tí ó kéré” náà pète “láti yí àwọn àkókò àti òfin padà.”

28. Báwo ni “àkókò kan, àti àwọn àkókò àti ààbọ̀ àkókò” náà ṣe gùn tó?

28 Áńgẹ́lì Jèhófà tọ́ka sí sáà alásọtẹ́lẹ̀ kan tí ó jẹ́ ti “àkókò kan, àti àwọn àkókò àti ààbọ̀ àkókò.” Báwo ni ìyẹn ṣe gùn tó? Àwọn alálàyé lórí Bíbélì gbà ní gbogbo gbòò pé gbólóhùn yìí túmọ̀ sí àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀—ríro àkókò kan pọ̀ mọ́ àkókò méjì àti ààbọ̀ àkókò. Níwọ̀n bí ìṣirò “ìgbà méje” tí Nebukadinésárì fi sínwín ti jẹ́ ọdún méje, àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀ náà jẹ́ ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀. * (Dáníẹ́lì 4:16, 25) Bíbélì An American Translation kà pé: “A óò fi wọ́n lé e lọ́wọ́ fún ọdún kan, ọdún méjì, àti ààbọ̀ ọdún.” Ìtumọ̀ ti James Moffatt sọ pé: “Fún ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ ọdún.” Sáà kan náà ni a mẹ́nu kàn ní Ìṣípayá 11:2-7, tí ó sọ pé àwọn ẹlẹ́rìí Ọlọ́run yóò wàásù ní wíwọ aṣọ àpò ìdọ̀họ fún oṣù méjìlélógójì, tàbí ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà [1,260] ọjọ́, a óò sì wá pa wọ́n. Ìgbà wo ni sáà yìí bẹ̀rẹ̀, ìgbà wo ni ó sì parí?

29. Ìgbà wo ni ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀, báwo ni ó sì ṣe bẹ̀rẹ̀?

29 Àkókò ìdánwò ni Ogun Àgbáyé Kìíní jẹ́ fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Nígbà tí ọdún 1914 fi ń parí lọ, wọ́n ń retí inúnibíni. Ní ti gidi, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tilẹ̀ yàn fún ọdún 1915 ni ìbéèrè tí Jésù bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin lè mu nínú ago tí èmi ó mu?” A gbé e karí Mátíù 20:22, King James Version. Nípa bẹ́ẹ̀, bẹ̀rẹ̀ ní December 1914, àwùjọ kékeré ti àwọn ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn ń wọ “aṣọ àpò ìdọ̀họ” lọ wàásù.

30. Báwo ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ṣe fòòró àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní?

30 Bí ìgbòkègbodò ogun tí ó gbóná janjan ti ń lọ lọ́wọ́, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń bá àtakò tí ó túbọ̀ ń le sí i pàdé. A ju àwọn kan nínú wọn sẹ́wọ̀n. Àwọn aláṣẹ afìkàṣayọ̀ dá àwọn ènìyàn bí Frank Platt ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Robert Clegg ní Kánádà lóró. Ní February 12, 1918, Ìjọba Kánádà Lábẹ́ Àkóso Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì fòfin de ìdìpọ̀ keje ti ìwé Studies in the Scriptures (Ìkẹ́kọ̀ọ́ Nínú Ìwé Mímọ́), tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀ jáde tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ The Finished Mystery (Ohun Ìjìnlẹ̀ Tí A Ti Parí), àti àwọn ìwé ìléwọ́ tí a àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ The Bible Students Monthly (Ìtẹ̀jáde Olóṣooṣù ti Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì). Ní oṣù tí ó tẹ̀ lé e, Ẹ̀ka Ìdájọ́ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kéde pé pípín ìdìpọ̀ keje náà kiri kò bófin mu mọ́. Kí ni èyí yọrí sí? Họ́wù, ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí túlé kiri, wọ́n ń fi àṣẹ ìjọba kó ìwé tipátipá, wọ́n sì ń fọlọ́pàá kó àwọn olùjọsìn Jèhófà!

31. Ìgbà wo ni “àkókò kan, àti àwọn àkókò àti ààbọ̀ àkókò” náà dópin, báwo ni wọ́n sì ṣe dópin?

31 Fífòòró àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run dé òtéńté rẹ̀ ní June 21, 1918, nígbà tí a fẹ̀sùn èké dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ fún ààrẹ J. F. Rutherford, àti àwọn sàràkí-sàràkí nínú mẹ́ńbà Watch Tower Bible and Tract Society. Bí ìwo “tí ó kéré” náà ṣe gbìyànjú “láti yí àwọn àkókò àti òfin padà,” ó fòpin sí ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù tí a ṣètò. (Ìṣípayá 11:7) Nípa báyìí, sáà “àkókò kan, àti àwọn àkókò àti ààbọ̀ àkókò” tí a sọ tẹ́lẹ̀ náà dópin ní oṣù June ọdún 1918.

32. Èé ṣe tí o fi lè sọ pé ìwo “tí ó kéré” náà kò pa “àwọn ẹni mímọ́” náà rẹ́?

32 Ṣùgbọ́n, fífòòró tí ìwo “tí ó kéré” náà fòòró “àwọn ẹni mímọ́” kò pa wọ́n rẹ́. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá, lẹ́yìn tí ìgbòkègbodò àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró dáwọ́ dúró fún ìgbà kúkúrú, wọ́n sọjí, wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ sí wàásù lẹ́ẹ̀kan sí i. (Ìṣípayá 11:11-13) Ní March 26, 1919, a dá ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n, lẹ́yìn náà, a wá sọ fún wọn pé wọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn èké tí a fi kàn wọ́n. Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn náà, àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró wá bẹ̀rẹ̀ sí tún ètò ṣe láti bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò ní pẹrẹu. Àmọ́, kí ní ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ìwo “tí ó kéré” náà?

KÓÒTÙ ẸNI ỌJỌ́ ÀTAYÉBÁYÉ NÁÀ MÚ ÌJÓKÒÓ

33. (a) Ta ni Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé? (b) Kí ni “àwọn ìwé” tí a “ṣí” nínú Kóòtù ọ̀run?

33 Lẹ́yìn tí Dáníẹ́lì ti mẹ́nu kan àwọn ẹranko mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ó yíjú kúrò lọ́dọ̀ ẹranko kẹrin síbi ìran kan tí ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run. Ó rí i tí Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ dídányanran gẹ́gẹ́ bí Adájọ́. Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé náà kì í ṣe ẹlòmíràn. (Sáàmù 90:2) Bí Kóòtù ọ̀run ṣe mú ìjókòó, Dáníẹ́lì rí i tí a “ṣí àwọn ìwé.” (Dáníẹ́lì 7:9, 10) Níwọ̀n bí Jèhófà ti ń bẹ láti àtayébáyé kánrin, ó mọ gbogbo ìtàn ìran ènìyàn bí pé ṣe ni a kọ ọ́ sínú ìwé kan. Ó ṣàkíyèsí àwọn ẹranko ìṣàpẹẹrẹ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ó sì lè ṣèdájọ́ wọn lórí ohun tí wọ́n ṣe gẹ́lẹ́ nítorí ó ṣojú rẹ̀.

34, 35. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ìwo “tí ó kéré” náà àti àwọn agbára yòókù tí wọ́n dà bí ẹranko?

34 Dáníẹ́lì ń bá a lọ pé: “Mo ń wò ní àkókò yẹn nítorí ìró àwọn ọ̀rọ̀ kàbìtìkàbìtì tí ìwo náà ń sọ; mo ń wò títí a fi pa ẹranko náà, a sì pa ara rẹ̀ run, a sì fi í fún iná tí ń jó. Ṣùgbọ́n ní ti ìyókù àwọn ẹranko náà, a gba agbára ìṣàkóso wọn kúrò, a sì fún wọn ní ìwàláàyè tí a mú gùn sí i fún ìgbà kan àti àsìkò kan.” (Dáníẹ́lì 7:11, 12) Áńgẹ́lì náà sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Kóòtù sì ń bá a lọ láti jókòó, wọ́n sì gba agbára ìṣàkóso rẹ̀ kúrò níkẹyìn, kí a bàa lè pa á rẹ́ ráúráú, kí a sì pa á run pátápátá.”—Dáníẹ́lì 7:26.

35 Nípa àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run, Onídàájọ́ Ńlá náà, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Ilẹ̀ Ọba Róòmù, tí ó ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni ìjímìjí, ni yóò bá ìwo tí ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run tí ó sì fòòró “àwọn ẹni mímọ́” rẹ̀. Ìṣàkóso rẹ̀ kò lè máa wà lọ. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn jẹ̀kúrẹdí “ọba” tí ó rí bí ìwo, tí ó ti inú Ilẹ̀ Ọba Róòmù jáde, kò ní máa wà lọ pẹ̀lú. Àwọn agbára ìṣàkóso tí ó tinú agbára àwọn ẹranko àtẹ̀yìnwá yòókù dìde wá ńkọ́? Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe wí, a fún wọn ní ìwàláàyè tí a mú kí ó gùn sí i “fún ìgbà kan àti àsìkò kan.” Àwọn ènìyàn ṣì ń gbé ní ìpínlẹ̀ wọn títí di ọjọ́ wa yìí. Bí àpẹẹrẹ, orílẹ̀-èdè Iraq wà ní ìpínlẹ̀ Bábílónì ìgbàanì. Ilẹ̀ Páṣíà (Iran) àti ti Gíríìsì ṣì wà síbẹ̀. Àṣẹ́kù àwọn agbára ayé wọ̀nyí jẹ́ apá kan Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Àwọn ìjọba wọ̀nyí yóò pa run pẹ̀lú nígbà tí a bá pa agbára ayé ìkẹyìn run ráúráú. Gbogbo ìjọba ènìyàn ni yóò pa rẹ́ ráúráú nínú “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìṣípayá 16:14, 16) Ṣùgbọ́n, ta wá ni yóò ṣàkóso ayé?

ÌṢÀKÓSO TÍ Ó WÀ PẸ́ TÍTÍ TI WỌLÉ DÉ TÁN!

36, 37. (a) Ta ni “ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn” tọ́ka sí, ìgbà wo ni ó fara hàn nínú Kóòtù ọ̀run, fún ète wo sì ni? (b) Kí ni a gbé kalẹ̀ ní ọdún 1914 Sànmánì Tiwa?

36 Dáníẹ́lì kígbe pé: “Mo rí i nínú ìran òru, sì wò ó! ó ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà ọ̀run; ó sì wọlé wá sọ́dọ̀ Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé, wọ́n mú un wá, àní sún mọ́ iwájú Ẹni náà.” (Dáníẹ́lì 7:13) Nígbà tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, ó pe ara rẹ̀ ní “Ọmọ ènìyàn” láti fi hàn pé òun bá aráyé tan. (Mátíù 16:13; 25:31) Jésù sọ fún àwọn Sànhẹ́dírìn, tàbí kóòtù àwọn Júù gíga jù lọ pé: “Ẹ óò rí Ọmọ ènìyàn tí yóò jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára, tí yóò sì máa bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run.” (Mátíù 26:64) Nítorí náà, nínú ìran Dáníẹ́lì, Jésù Kristi tí a jí dìde, tí a ti ṣe lógo ni ẹni yẹn tí ń bọ̀, tí ènìyàn kò lè fojúrí, tí ó wọlé wá sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run. Ìgbà wo ni èyí ṣẹlẹ̀?

37 Ọlọ́run bá Jésù Kristi dá májẹ̀mú Ìjọba, gan-an bí ó ṣe bá Dáfídì Ọba dá májẹ̀mú pẹ̀lú. (2 Sámúẹ́lì 7:11-16; Lúùkù 22:28-30) Nígbà tí “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” dópin ní ọdún 1914 Sànmánì Tiwa, Jésù Kristi ní ẹ̀tọ́ láti gba ìṣàkóso Ìjọba nítorí ó jẹ́ ajogún ìtẹ́ Dáfídì. Àkọsílẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì kà pé: “A . . . fún un ní agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun. Agbára ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ agbára ìṣàkóso tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin tí kì yóò kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ sì jẹ́ èyí tí a kì yóò run.” (Dáníẹ́lì 7:14) Bí a ṣe gbé Ìjọba Mèsáyà kalẹ̀ ní ọ̀run ní ọdún 1914 nìyẹn. Àmọ́, a tún fún àwọn mìíràn ní ìṣàkóso náà pẹ̀lú.

38, 39. Ta ni yóò gba ìṣàkóso àìnípẹ̀kun lórí ayé?

38 Áńgẹ́lì náà sọ pé: “Àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ yóò gba ìjọba.” (Dáníẹ́lì 7:18, 22, 27) Jésù Kristi ni olórí ẹni mímọ́. (Ìṣe 3:14; 4:27, 30) “Àwọn ẹni mímọ́” yòókù tí ó nípìn-ín nínú ìṣàkóso yẹn ni àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jẹ́ Kristẹni olùṣòtítọ́, àwọn ẹni àmì òróró tí a fẹ̀mí yàn, tí wọ́n jẹ́ ajùmọ̀jogún Ìjọba pẹ̀lú Kristi. (Róòmù 1:7; 8:17; 2 Tẹsalóníkà 1:5; 1 Pétérù 2:9) A jí wọn dìde nínú ikú gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀mí aláìleèkú tí yóò ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lórí Òkè Síónì ti ọ̀run. (Ìṣípayá 2:10; 14:1; 20:6) Nípa báyìí, Kristi Jésù àti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí a jí dìde yóò ṣàkóso ayé aráyé.

39 Áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ nípa ìṣàkóso Ọmọ ènìyàn àti “àwọn ẹni mímọ́” yòókù tí a jí dìde pé: “Ìjọba àti agbára ìṣàkóso àti ìtóbilọ́lá àwọn ìjọba lábẹ́ gbogbo ọ̀run ni a sì fi fún àwọn tí í ṣe ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ. Ìjọba wọ́n jẹ́ ìjọba tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní àwọn ni gbogbo agbára ìṣàkóso yóò máa sìn, tí wọn yóò sì ṣègbọràn sí.” (Dáníẹ́lì 7:27) Ìbùkún tí aráyé onígbọràn yóò rí gbà lábẹ́ Ìjọba yẹn yóò mà pọ̀ o!

40. Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní bí a bá kíyè sí àlá àti àwọn ìran Dáníẹ́lì?

40 Dáníẹ́lì kò mọ̀ nípa gbogbo ìmúṣẹ àgbàyanu tí ìran tí Ọlọ́run jẹ́ kí ó rí yóò ní. Ó sọ pé: “Títí dé orí kókó yìí ni òpin ọ̀ràn náà. Ní ti èmi, Dáníẹ́lì, ìrònú mi kó jìnnìjìnnì bá mi gidigidi, tí àwọ̀ ara mi fi yí padà lára mi; ṣùgbọ́n ọ̀ràn náà ni mo pa mọ́ sínú ọkàn-àyà mi.” (Dáníẹ́lì 7:28) Ṣùgbọ́n, ní tiwa, àwa ń gbé ní àkókò tí a lè lóye ìmúṣẹ ohun tí Dáníẹ́lì rí. Kíkíyèsí àsọtẹ́lẹ̀ yìí yóò fún ìgbàgbọ́ wa lókun, yóò sì fún ìdánilójú tí a ní pé Mèsáyà, Ọba tí Jèhófà fi jẹ yóò ṣàkóso ayé.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 4 Kí àlàyé wa bàa lè ṣe kedere kí a sì yẹra fún àsọtúnsọ, a óò mú àwọn ẹsẹ tí ó jẹ́ àlàyé nínú Dáníẹ́lì 7:15-28 wọnú àgbéyẹ̀wò ẹsẹ-ẹsẹ tí a óò ṣe lórí àwọn ìran tí a kọ sínú Dáníẹ́lì 7:1-14.

^ ìpínrọ̀ 7 Wo Orí Kẹrin ìwé yìí.

^ ìpínrọ̀ 28 Wo Orí Kẹfà ìwé yìí.

KÍ LO LÓYE?

• Kí ni ọ̀kọ̀ọ̀kan ‘àwọn ẹranko mẹ́rin tí ó tóbi fàkìàfakia tí ó jáde wá láti inú òkun’ ṣàpẹẹrẹ?

• Kí ni ó para pọ̀ jẹ́ ìwo “tí ó kéré” náà?

• Báwo ni ìwo kékeré ìṣàpẹẹrẹ náà ṣe fòòró “àwọn ẹni mímọ́” nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní?

• Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ìwo kékeré ìṣàpẹẹrẹ náà àti àwọn agbára yòókù tí wọ́n dà bí ẹranko?

• Báwo ni o ṣe jàǹfààní láti inú ṣíṣàkíyèsí àlá àti àwọn ìran Dáníẹ́lì nípa “ẹranko mẹ́rin tí ó tóbi fàkìàfakia” náà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 149-152]

ỌBA TÍ KÌ Í FI NǸKAN NINI LÁRA

ÒǸKỌ̀WÉ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa rántí pé ó jẹ́ ọba dáadáa tí kì í fi nǹkan nini lára. Nínú Bíbélì a pè é ní “ẹni àmì òróró” Ọlọ́run àti “ẹyẹ aṣọdẹ” tí ó wá láti ìhà “yíyọ oòrùn.” (Aísáyà 45:1; 46:11) Kírúsì Ńlá ti ilẹ̀ Páṣíà ni ọba tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́nà yìí.

Ìgbésẹ̀ tí ó sọ Kírúsì di olókìkí bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 560 sí 559 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí ó rọ́pò baba rẹ̀ Kanbáísísì Kìíní, lórí ìtẹ́ ìlú Anshan, ìlú ńlá kan tàbí àgbègbè kan ní ilẹ̀ Páṣíà ìgbàanì. Abẹ́ àbójútó Ásítíyágè ọba Mídíà ni ìlú Anshan wà nígbà náà. Kírúsì ṣọ̀tẹ̀ sí ìṣàkóso Mídíà, ó sì borí kíákíá nítorí pé àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásítíyágè ya lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, àwọn ará Mídíà wá dúró ṣinṣin ti Kírúsì. Lẹ́yìn náà ni àwọn ará Mídíà àti Páṣíà wá jùmọ̀ ń jagun pa pọ̀ lábẹ́ ìdarí rẹ̀. Bí ìṣàkóso Mídíà òun Páṣíà ṣe wáyé nìyẹn, kí àgbègbè ìṣàkóso rẹ̀ tó wá gbilẹ̀ sí i láti Òkun Aegean títí dé Odò Indus níkẹyìn.—Wo àwòrán ilẹ̀.

Bí Kírúsì ṣe kó àpapọ̀ agbo ọmọ ogun àwọn ará Mídíà òun Páṣíà sòdí, ó kọ́kọ́ lọ fi àkóso múlẹ̀ ní ibi tí ìjàngbọ̀n wà—apá ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Mídíà níbi tí Kiroésù Ọba, ti ilẹ̀ Lídíà, ti ń nasẹ̀ àgbègbè ìṣàkóso rẹ̀ wọnú ìpínlẹ̀ Mídíà. Bí Kírúsì ṣe tẹ̀ síwájú síhà ààlà Ilẹ̀ Ọba Lídíà níhà ìlà oòrùn ní Éṣíà Kékeré, ó ṣẹ́gun Kiroésù, ó sì gba Sádísì tí ó jẹ́ olú ìlú rẹ̀. Kírúsì wá ṣẹ́gun àwọn ìlú ńlá Ionia, ó sì sọ gbogbo Éṣíà Kékeré di ara àgbègbè Ilẹ̀ Ọba Mídíà òun Páṣíà. Ó wá tipa báyìí di ògúnná gbòǹgbò nínú àwọn tí ń bá ilẹ̀ Bábílónì àti Nábónídọ́sì ọba rẹ̀ figẹ̀ wọngẹ̀.

Kírúsì wá gbára dì láti lọ gbéjà ko ilẹ̀ Bábílónì alágbára ńlá. Láti orí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí síwájú ni ó sì ti di ọ̀kan nínú àwọn tí ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. Ní nǹkan bí ọ̀rúndún méjì ṣáájú, Jèhófà ti tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà dárúkọ Kírúsì gẹ́gẹ́ bí alákòóso tí yóò gbàjọba mọ́ Bábílónì lọ́wọ́ tí yóò sì tú àwọn Júù sílẹ̀ nígbèkùn. Nítorí yíyàn tí a yàn án ṣáájú yìí ni Ìwé Mímọ́ fi tọ́ka sí Kírúsì gẹ́gẹ́ bí “ẹni àmì òróró” Jèhófà.—Aísáyà 44:26-28.

Nígbà tí Kírúsì gòkè wá gbéjà ko Bábílónì ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, iṣẹ́ bàǹtàbanta kan dojú kọ ọ́. Ìlú ńlá náà dà bí èyí tí a kò lè ṣẹ́gun nítorí pé àwọn odi ràgàjì ràgàjì àti yàrà oníbú jíjìn tí omi odò Yúfírétì kún ni ó yí i po. Ṣe ni a mọ odi tí ó ga bí òkè sí ibi tí odò Yúfírétì ti ṣàn la Bábílónì kọjá, tí a sì ṣe àwọn ẹnubodè bàbà gbàràmù gbàràmù sí àwọn etídò rẹ̀. Báwo ni yóò ṣe wá ṣeé ṣe pé kí Kírúsì gba Bábílónì?

Ní ohun tí ó ju ọ̀rúndún kan ṣáájú ìgbà náà, Jèhófà ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ pé “ìparundahoro” yóò “wà lórí omi rẹ̀,” ó sì ti sọ pé “a ó gbẹ ẹ́ táútáú.” (Jeremáyà 50:38) Gẹ́lẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe wí, ṣe ni Kírúsì darí omi Odò Yúfírétì gba ibòmíràn ní nǹkan bí kìlómítà mélòó kan níhà àríwá Bábílónì. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wá wọ́ ìsàlẹ̀ odò náà kọjá, wọ́n pọ́nkè gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tí ó lọ síbi odi, wọ́n sì wọ ìlú náà lọ tìrọ̀rùntìrọ̀rùn, nítorí pé ńṣe ni wọ́n ṣí àwọn ẹnubodè bàbà wọ̀nyẹn kalẹ̀. Bí “ẹyẹ aṣọdẹ” tí ó fò mọ́ ẹran ìjẹ rẹ̀ lójijì mà ló rí o, alákòóso yìí láti “yíyọ oòrùn”—láti ìlà oòrùn—gba Bábílónì ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo!

Ní ti àwọn Júù tí ó wà ní Bábílónì, ṣíṣẹ́gun tí Kírúsì ṣẹ́gun yìí fi hàn pé ìdásílẹ̀ kúrò nígbèkùn tí wọ́n ti ń retí tipẹ́tipẹ́ ti dé, pé ìsọdahoro tí ó bá ìlú ìbílẹ̀ wọn láti àádọ́rin ọdún wá ti dópin. Ẹ wo bí inú wọn ṣe máa dùn tó nígbà tí Kírúsì gbé ìkéde jáde pé a fún wọn láṣẹ láti padà sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n sì tún tẹ́ńpìlì rẹ̀ kọ́! Kírúsì tún dá àwọn ohun èlò iyebíye inú tẹ́ńpìlì tí Nebukadinésárì kó wá sí Bábílónì padà fún wọn, ó sì fún wọn ní ìyọ̀ǹda láti ọ̀dọ̀ ọba pé kí wọ́n kó gẹdú wá láti Lẹ́bánónì, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n fún wọn ní owó láti ilé ọba láti lè fi bójú tó ìnáwó iṣẹ́ ìkọ́lé náà.—Ẹ́sírà 1:1-11; 6:3-5.

Ní gbogbo gbòò, ìwà kí a gba ti ẹlòmíràn rò àti kí a má fi nǹkan nini lára ni Kírúsì máa ń hù sí àwọn ènìyàn tí ó bá ṣẹ́gun. Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀sìn rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ìdí tí ó fi ń hùwà bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé àwọn ẹ̀kọ́ wòlíì Soroásítà ará Páṣíà náà ni Kírúsì rọ̀ mọ́, kí ó sì máa sin Ahura Másídà—ọlọ́run kan tí wọ́n rò pé ó ṣẹ̀dá ohun rere gbogbo. Farhang Mehr kọ sínú ìwé rẹ̀ The Zoroastrian Tradition pé: “Soroásítà gbé Ọlọ́run kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìjẹ́pípé ní ti ìwà rere. Ó sọ fún àwọn ènìyàn pé Ahura Másídà kì í foró yáró ṣùgbọ́n pé ó jẹ́ onídàájọ́ òdodo, nítorí náà, kì í ṣe ẹni tí ó yẹ kí a máa bẹ̀rù bí kò ṣe pé kí a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Ó ṣeé ṣe kí ìgbàgbọ́ Kírúsì nínú ọlọ́run oníwà rere àti onídàájọ́ òdodo ti nípa lórí ìlànà ìwà híhù rẹ̀, tí ó sì ń mú kí ó máa hùwà ẹni tí ó rí ara gba nǹkan àti ìwà tí ó tọ́.

Ṣùgbọ́n ọba náà kò lè fara da ipò ojú ọjọ́ ní Bábílónì. Ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí ó móoru gidigidi ti tayọ ohun tí ó lè fara dà. Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bábílónì ṣì jẹ́ ìlú ọba fún ilẹ̀ ọba náà, tí ó sì tún jẹ́ ibi tí ẹ̀sìn àti ohun ìṣẹ̀ǹbáyé kórí jọ sí, kìkì ìgbà òtútù ni ó ń lò ó gẹ́gẹ́ bí olú ìlú. Ní ti gidi, lẹ́yìn tí Kírúsì ṣẹ́gun Bábílónì, kò pẹ́ tí ó fi padà sí Ekibátánà tí ó fi ṣe olú ìlú rẹ̀ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, ó wà ní ibi tí ó fi nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá [1,900] mítà yọ sókè ju ìtẹ́jú òkun, ní ìsàlẹ̀ Òkè Alwand. Bí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn atunilára ṣe tẹ̀ lé ìgbà òtútù tí ó tutù nini túbọ̀ tù ú lára jù. Kírúsì tún kọ́ ààfin tí ó pinminrin kan sí ìlú Pasagádáè (nítòsí Persepolis), olú ìlú rẹ̀ tẹ́lẹ̀, tí ó wà ní nǹkan bí ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó dín mẹ́wàá [650] kìlómítà níhà gúúsù ìlà-oòrùn Ekibátánà. Ibùgbé tí ó wà níbẹ̀ ni ó fi ṣe ibi ìsinmi.

Nípa báyìí, ìwà akọni aṣẹ́gun àti ti ọba tì kì í fi nǹkan nini lára ni ànímọ́ tí a fi ń rántí Kírúsì. Ó kú ní ọdún 530 ṣááju Sànmánì Tiwa nígbà tí ó wà lẹ́nu ogun jíjà kiri, èyí ló sì fòpin sí ìṣàkóso tí ó ṣe fún ọgbọ̀n ọdún. Ọmọ rẹ̀ Kanbáísísì Kejì sì rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́ ilẹ̀ Páṣíà.

KÍ LO LÓYE?

• Báwo ni Kírúsì ará Páṣíà ṣe jẹ́ “ẹni àmì òróró” Jèhófà?

• Iṣẹ́ pàtàkì wo ni Kírúsì ṣe fún àwọn ènìyàn Jèhófà?

• Irú ìwà wo ni Kírúsì máa ń hù sí àwọn tí ó bá ṣẹ́gun?

[Àwòrán ilẹ̀]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ILẸ̀ ỌBA MÍDÍÀ ÒUN PÁṢÍÀ

MAKEDÓNÍÀ

Mémúfísì

ÍJÍBÍTÌ

ETIÓPÍÀ

Jerúsálẹ́mù

Bábílónì

Ekibátánà

Súsà

Persepolis

ÍŃDÍÀ

[Àwòrán]

Ibojì Kírúsì, ní Pasagádáè

[Àwòrán]

Àwòrán tí a gbẹ́ ní Pasagádáè, tí ń ṣàfihàn Kírúsì

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 153-161]

Ọ̀DỌ́ ỌBA KAN ṢẸ́GUN AYÉ

NÍ NǸKAN bí ẹ̀ẹ́dégbèjìlá [2,300] ọdún sẹ́yìn, ọ̀gágun onírun aláwọ̀ góòlù kan, tí ọjọ́ orí rẹ̀ ti lé lógún ọdún, dúró sí etíkun Òkun Mẹditaréníà. Ó dójú lé ìlú ńlá tí ó wà ní erékùṣù kan ní nǹkan bí kìlómítà kan síwájú. Bí wọn kò ti gbà á láyè láti wọ ibẹ̀, ọ̀gágun tí inú rẹ̀ ti ru yìí pinnu láti ṣẹ́gun ìlú náà. Kí ni ìwéwèé ogun tí yóò lò? Yóò ṣe afárá kan lọ sí erékùṣù náà, yóò sì dojú agbo ọmọ ogun rẹ̀ kọ ìlú náà. Iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ lórí afárá náà.

Ṣùgbọ́n ìhìn iṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ ọba ńlá ti Ilẹ̀ Ọba Páṣíà dá ọ̀dọ́ ọ̀gágun yìí dúró díẹ̀. Bí alákòóso ilẹ̀ Páṣíà náà ti ń hára gàgà láti wá àlàáfíà, ó ṣe ìpèsè àrà ọ̀tọ̀ kan: ẹgbàárùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà (ó ju bílíọ̀nù méjì dọ́là lọ lójú ìdiwọ̀n ti lọ́ọ́lọ́ọ́), ó fa ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ kalẹ̀ kí a fi ṣaya, ó sì yọ̀ǹda ìṣàkóso lórí gbogbo ìhà ìwọ̀ oòrùn Ilẹ̀ Ọba Páṣíà. Ó pèsè gbogbo ìwọ̀nyí láti lè rí ìdílé ọba, tí ọ̀gágun náà ti mú lóǹdè gbà padà.

Ọ̀gágun tí ó dojú kọ ìpinnu lórí bóyá kí ó gba ìpèsè yìí tàbí kí ó má gbà á ni Alẹkisáńdà Kẹta ti ilẹ̀ Makedóníà. Ṣé kí ó gba ìpèsè yẹn ni? Òpìtàn náà, Ulrich Wilcken, sọ pé: “Ó jẹ́ àkókò kan tí ọ̀ràn dórí kókó ní ayé ìgbàanì. Ní ti gidi, àbájáde ìpinnu rẹ̀ yìí, lọ jìnnà ré kọjá Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú títí dé ọjọ́ wa lónìí, ní ìhà Ìlà Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrùn Ayé.” Kí a tó gbé ohun tí Alẹkisáńdà fi fèsì yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ kí a wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó mú kí ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí wáyé.

BÍ Ó ṢE DI AṢẸ́GUN

Ìlú Pella ní Makedóníà ni a ti bí Alẹkisáńdà lọ́dún 356 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ọba Fílípì Kejì ni baba rẹ̀, Ólíńpíásì sì ni ìyá rẹ̀. Ìyá Alẹkisáńdà kọ́ ọ pé láti ọ̀dọ̀ Hákúlísì, ọmọ Súúsì, ọlọ́run àwọn Gíríìkì ni àwọn ọba ilẹ̀ Makedóníà ti ṣẹ̀ wá. Gẹ́gẹ́ bí Ólíńpíásì ṣe wí, Ákílísì, tí ó jẹ́ akọni inú ewì Homer náà, Iliad, ni baba ńlá Alẹkisáńdà. Bí àwọn òbí Alẹkisáńdà ṣe tipa báyìí fi ẹ̀mí ìlépa ìṣẹ́gun àti ògo ọba kọ́ ọ, kò wá tún sí ohun mìíràn tí ó fi bẹ́ẹ̀ wù ú láti lépa mọ́. Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Alẹkisáńdà bóyá yóò kópa nínú àwọn Eré Ìdárayá ti Olympic, ó ní òun yóò ṣe bẹ́ẹ̀ bí ó bá ṣe pé àwọn ọba ni òun fẹ́ bá sáré pọ̀. Ohun tí ó ń lépa ni kí ó lè gbé àwọn ohun ńláńlá ṣe ré kọjá ti baba rẹ̀ kí ó sì gbògo láti inú àwọn àṣeyọrí tí ó bá ṣe.

Nígbà tí Alẹkisáńdà jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá, ó rí ẹ̀kọ́ gbà láti ọ̀dọ̀ ọlọ́gbọ́n èrò orí, ará Gíríìkì náà, Aristotle, ẹni tí ó mú kí ó nífẹ̀ẹ́ sí ọgbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn, ẹ̀kọ́ nípa egbòogi, àti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Àríyànjiyàn ṣì wà ní ti báwo ni àwọn ẹ̀kọ́ ọgbọ́n èrò orí Aristotle ṣe nípa lórí ìrònú Alẹkisáńdà tó. Ọlọ́gbọ́n èrò orí ti ọ̀rúndún ogún náà, Bertrand Russell, sọ pé: “Kí a sáà kúkú sọ pé ibi tí ọ̀rọ̀ wọn ti wọra kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Aristotle gbé ojú ìwòye tirẹ̀ nípa ìṣèlú karí ìlànà àwọn Gíríìkì ti pé kí ọba kọ̀ọ̀kan ṣàkóso ìlú ńlá kan àti ìgbèríko rẹ̀, ìlànà náà sì ti ń kásẹ̀ nílẹ̀.” Èrò ti pé ká ṣèjọba kélébé lórí ìlú ńlá kan ṣoṣo kò lè wu ọmọ ọba kan tí ó jẹ́ olùlépa àṣeyọrí, tí ó fẹ́ láti ní ilẹ̀ ọba tí ó gbòòrò, tí a ń darí láti ibì kan ṣoṣo. Ó ṣeé ṣe kí Alẹkisáńdà sì tún ṣiyèméjì nípa èrò Aristotle náà pé ìlò ẹrú ni kí a máa lo gbogbo àwọn tí kì í ṣe Gíríìkì, nítorí pé, irú ilẹ̀ ọba kan tí ó ń fojú sọ́nà fún lọ́jọ́ iwájú ni èyí tí àjọṣe tí ó dára yóò ti máa bá a lọ láàárín àwọn aṣẹ́gun àti àwọn tí a ṣẹ́gun.

Àmọ́, kò sí àní-àní pé Aristotle gbin ẹ̀mí ìwé kíkà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ sínú Alẹkisáńdà. Òǹkàwé paraku ni Alẹkisáńdà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ sí kíka àwọn ìwé Homer. Àwọn kan sọ pé ó mọ ewì Iliad sórí, ìyẹn gbogbo ẹsẹ ẹgbàáje lé lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sàn-án ó dín méje [15,693] tí ewì náà ní.

Ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ lọ́dọ̀ Aristotle dópin lójijì lọ́dún 340 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí ọmọ ọba, ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún náà, padà sí Pella láti ṣàkóso Makedóníà gẹ́gẹ́ bí adelé fún baba rẹ̀. Kò sì pẹ́ tí ọmọ aládé yìí fi yọrí bí akin lójú ogun. Kíá ni ó paná ọ̀tẹ̀ àwọn ẹ̀yà Maedi ti Tírésì, ẹyẹ-ò-sọkà ló gba olú ìlú wọn, ó sì sọ ọ́ ní Alexandroúpolis, níbàámu pẹ̀lú orúkọ ara rẹ̀, ìwọ̀nyí sì dùn mọ́ Fílípì nínú.

Ó Ń BÁ ÌṢẸ́GUN NÌṢÓ

Yíyọ́ tí wọ́n yọ́ kẹ́lẹ́ pa Fílípì ní ọdún 336 ṣááju Sànmánì Tiwa mú kí Alẹkisáńdà, ẹni ogún ọdún, jogún ìtẹ́ ilẹ̀ Makedóníà. Nígbà tí Alẹkisáńdà gba ti ipadò Hellespont (tí ó di Dardanelles nísinsìnyí) wọ Éṣíà ní ìgbà ìrúwé ọdún 334 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó bẹ̀rẹ̀ sí ja ogun àjàṣẹ́gun kiri, ní lílo ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] ọmọ ogun tí ń fẹsẹ̀ rìn àti ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [5,000] agẹṣinjagun, tí ó jẹ́ pé wọ́n kéré níye ṣùgbọ́n wọ́n jáfáfá. Tòun ti àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ rẹ̀, àwọn tí ń wọnlẹ̀, olùyàwòrán ìgbékalẹ̀ ilé, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti àwọn òpìtàn ni wọ́n jọ ń lọ.

Ibi Odò Gíráníkọ́sì níhà àríwá ìwọ̀ oòrùn Éṣíà Kékeré (tí í ṣe ilẹ̀ Turkey ìsinsìnyí), ni Alẹkisáńdà ti kọ́kọ́ ṣẹ́gun ogun tí ó bá àwọn ará Páṣíà jà. Ní ìgbà òtútù ọdún yẹn, ó ṣẹ́gun ìwọ̀ oòrùn Éṣíà Kékeré. Ìgbà ìwọ́wé tí ó tẹ̀ lé èyí, ó bá àwọn ará Páṣíà ja ogun àjàmọ̀gá ẹlẹ́ẹ̀kejì ní ìlú Issus, níhà gúúsù ìlà oòrùn Éṣíà Kékeré. Ọba Páṣíà ńlá náà, Dáríúsì Kẹta, kó nǹkan bí ìdajì mílíọ̀nù ọmọ ogun wá pàdé Alẹkisáńdà níbẹ̀. Nítorí pé Dáríúsì dá ara rẹ̀ lójú jù, ó tún mú ìyá rẹ̀, aya rẹ̀, àti àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ mìíràn dání wá, kí ìṣẹ́gun àrà ọ̀tọ̀ tí ó rò pé yóò jẹ́ tòun lè ṣojú wọn. Ṣùgbọ́n yíyọ tí àwọn ará Makedóníà yọ ní ìjafùú sí àwọn ará Páṣíà àti bí wọ́n ṣe bá wọn jagun lọ́nà líle bá wọn lábo. Agbo ọmọ ogun Alẹkisáńdà ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Páṣíà pátápátá, Dáríúsì sì fẹsẹ̀ fẹ, ó jọ̀wọ́ ìdílé rẹ̀ fún Alẹkisáńdà.

Dípò tí Alẹkisáńdà ì bá fi máa lépa àwọn ará Páṣíà tí ó fẹsẹ̀ fẹ, ó gba ọ̀nà gúúsù lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Etíkun Mẹditaréníà, ó sì ṣẹ́gun àwọn ibùdó ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun alágbára tí ilẹ̀ Páṣíà ń lò. Àmọ́, ìlú ńlá Tírè, tí ó jẹ́ erékùṣù, dènà ogun tí ó fẹ́ gbé wá jà wọ́n. Níwọ̀n bí Alẹkisáńdà ti pinnu láti ṣẹ́gun rẹ̀, ó bá dó tì í títí di oṣù méje. Ìgbà ìdótì náà ni Dáríúsì kó àwọn ìpèsè láti fi wá àlàáfíà, èyí tí a mẹ́nu kàn ṣáájú wá. Àwọn ohun tí Dáríúsì gbà láti ṣe fani mọ́ra tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a fi ròyìn rẹ̀ pé, Parmenio, alábàádámọ̀ràn tí Alẹkisáńdà gbẹ́kẹ̀ lé, sọ pé: ‘Ká ní èmi ni Alẹkisáńdà, èmi yóò gbà á.’ Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́ ọ̀gágun náà fi ìkanra sọ pé: ‘Ohun tí èmi náà ì bá ṣe nìyẹn, ká ní èmi ni Parmenio.’ Alẹkisáńdà kò gbà láti dúnàádúrà, ó sì ń bá ìdótì rẹ̀ lọ, ó sì wó Tírè, agbéraga ìlú àárín òkun, palẹ̀ ní July ọdún 332 ṣááju Sànmánì Tiwa.

Alẹkisáńdà dá Jerúsálẹ́mù tí ó túúbá fún un sí, ó gbógun gba ìhà gúúsù lọ, ó sì ṣẹ́gun ìlú Gásà. Ṣe ni àwọn ará Íjíbítì tẹ́wọ́ gbà á bí olùdáǹdè nítorí pé ìṣàkóso àwọn ará Páṣíà ti sú wọn. Ó rúbọ sí akọ màlúù Apis ní ìlú Mémúfísì, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú inú àwọn àlùfáà Íjíbítì dùn. Ó tún kọ́ ìlú Alẹkisáńdíríà, èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ bá Áténì dọ́gba gẹ́gẹ́ bí ojúkò ẹ̀kọ́ kíkọ́, orúkọ yẹn ló ṣì ń jẹ́ di báyìí.

Lẹ́yìn èyí, Alẹkisáńdà kọjú sí ìhà àríwá ìlà oòrùn, ó la Palẹ́sìnì kọjá, ó sì gba ti Odò Tígírísì lọ. Lọ́dún 331 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó bá àwọn ará Páṣíà ja ogun ńlá kẹta ní Gaugamela, nítòsí àwọn àwókù Nínéfè. Níhìn-ín ni àwọn ènìyàn Alẹkisáńdà tí ó jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin [47,000] ti borí àwọn ọmọ ogun Páṣíà tí ó ti lọ túnra mú, tí wọ́n sì tó ọ̀kẹ́ méjìlá ààbọ̀ [250,000] ó kéré tán! Dáríúsì bá fẹsẹ̀ fẹ, àwọn ènìyàn rẹ̀ sì ṣìkà pa á lẹ́yìn náà.

Bí ìṣẹ́gun ti mú ara Alẹkisáńdà yá gágá, ló bá yíjú síhà gúúsù, ó sì gba Bábílónì, tí ilẹ̀ Páṣíà fi ń ṣe olú ìlú ní ìgbà òtútù. Ó tún gba Súsà àti Persepolis, tí wọ́n jẹ́ olú ìlú, ó sì gba ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ibi ìṣúra ilẹ̀ Páṣíà, ó sì dáná sún ààfin ńlá tí ó jẹ́ tí Sásítà. Níkẹyìn, olú ìlú tí ó wà ní Ekibátánà bọ́ sí i lọ́wọ́. Ẹni tí ń ṣẹ́gun ní wàràǹwéré yìí wá borí gbogbo àgbègbè ìṣàkóso Páṣíà, ó sì lọ jìnnà níhà ìlà oòrùn títí dé Odò Indus, tí ó wà ní ilẹ̀ Pakistan òde òní.

Bí Alẹkisáńdà ṣe ré kọjá odò Indus, ní àgbègbè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Tásílà tí ó jẹ́ ara ẹkùn ìpínlẹ̀ Páṣíà, ó bá abánidíje kan tí ó le kú pàdé, ìyẹn Porus, ọba Íńdíà. Òun ni Alẹkisáńdà bá ja ogun pàtàkì rẹ̀ kẹrin, tí ó sì jẹ́ àjàkẹ́yìn rẹ̀, ní June ọdún 326 ṣááju Sànmánì Tiwa. Àwọn ọmọ ogun Porus jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [35,000] sójà àti igba erin tí ó dáyà já ẹṣin àwọn ará Makedóníà. Ogun yẹn le kú, ó sì mú ìtàjẹ̀sílẹ̀ púpọ̀ lọ́wọ́, àmọ́ agbo ọmọ ogun Alẹkisáńdà borí. Porus bá túúbá fún un, wọ́n sì jùmọ̀ di alájọṣe.

Ó ti ju ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Makedóníà tí sọdá wá sí Éṣíà, ó sì ti rẹ àwọn ọmọ ogun, ọkàn wọn sì ń fà sílé. Bí ogun líle tí Porus bá wọn jà ti mu wọ́n lómi, wọ́n fẹ́ padà sílé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Alẹkisáńdà kò fẹ́ gbà lákọ̀ọ́kọ́, ó fara mọ́ ohun tí wọ́n fẹ́. Ní ti gidi, ilẹ̀ Gíríìkì ti di agbára ayé. Bí ó ti jẹ́ pé ń ṣe ni wọ́n ń dá àwọn ìlú tí àwọn Gíríìkì dá dó sí, sílẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ṣẹ́gun, èdè Gíríìkì àti àṣà wọn tàn ká gbogbo àgbègbè tí wọ́n ń ṣàkóso.

ẸNI TÍ Ó JẸ́ IGI LẸ́YÌN ỌGBÀ ÀWỌN ỌMỌ OGUN NÁÀ

Ìwà Alẹkisáńdà ni ó so àwọn ọmọ ogun Makedóníà pa pọ̀ ní gbogbo ọdún tí wọ́n fi ń ṣẹ́gun. Ó jẹ́ àṣà Alẹkisáńdà pé lẹ́yìn ìjà ogun, yóò lọ bẹ àwọn tí wọ́n bá fara pa wò, yóò ṣàyẹ̀wò ọgbẹ́ wọn, yóò yin àwọn ọmọ ogun lórí ìṣe akíkanjú wọn, yóò sì bọlá fún wọn nípa fífún wọn ní ẹ̀bùn níbàámu pẹ̀lú àṣeyọrí wọn. Ní ti àwọn tí wọ́n bá kú lójú ìjà, Alẹkisáńdà a ṣètò ààtò ìsìnkú tí ó pẹtẹrí fún wọn. Àwọn òbí àti ọmọ àwọn tí ó kú lójú ogun kò ní san owó orí èyíkéyìí, wọn kò sì ní ṣe iṣẹ́ ọba èyíkéyìí mọ́. Alẹkisáńdà máa ń dá eré ìdárayá àti ìdíje sílẹ̀ láti fi ṣe ohun ìnàjú lẹ́yìn ogun. Ní ìgbà kan, ó tilẹ̀ fún àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, kí wọ́n bàa lè lọ lo ìgbà òtútù lọ́dọ̀ ìyàwó wọn ní Makedóníà. Àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyẹn ló jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ kí ó sì gbayì lọ́dọ̀ wọn.

Pílútákì ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì, tí ó jẹ́ akọ̀tàn ìgbésí ayé ẹni, kọ̀wé nípa bí Alẹkisáńdà ṣe gbé Rokisánà, ọmọ ọba ìlú Bákítìrì níyàwó pé: “Ìfẹ́ ló kó sí i lórí lóòótọ́, síbẹ̀, ó dà bí pé ó bá góńgó rẹ̀ mu lẹ́sẹ̀ kan náà. Nítorí pé, ìwúrí ni ó jẹ́ fún àwọn tí a ṣẹ́gun wọn pé ó lè fẹ́ aya láti ọ̀dọ̀ wọn, ó sì mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gidigidi, bí wọ́n ti rí i pé ìwà ọmọlúwàbí tirẹ̀ tayọ ní ti pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ ràdọ̀ bò ó, síbẹ̀ ó fara dà á títí obìnrin náà fi tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ lọ́nà tí ó bófin mu tí ó sì bọlá fúnni.”

Alẹkisáńdà tún bọ̀wọ̀ fún ìgbéyàwó àwọn ẹlòmíràn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣe ni ó mú aya Dáríúsì Ọba lóǹdè, ó rí i dájú pé ìwà ọ̀wọ̀ ni a ń hù sí i. Bákan náà, nígbà tí ó gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun Makedóníà méjì bá aya àwọn àjèjì kan ṣe ìṣekúṣe, ó pàṣẹ pé kí a pa wọ́n bí wọ́n bá jẹ̀bi.

Alẹkisáńdà jẹ́ ẹlẹ́sìn paraku bí ti Ólíńpíásì ìyá rẹ̀. A máa rúbọ kí ó tó jagun, a sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn ogun, a máa kàn sí àwọn woṣẹ́woṣẹ́ nípa ìjẹ́pàtàkì àwọn àpẹẹrẹ abàmì. Ó tún kàn sí ilé awo Ámónì ní ilẹ̀ Líbíà. Ní Bábílónì, ó ṣe gbogbo ohun tí ìtọ́ni àwọn ará Kálídíà sọ nípa ìrúbọ, pàápàá ní ti Bélì (Mádọ́kì), ọlọ́run Bábílónì.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Alẹkisáńdà máa ń jẹun níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó padà wá di onímukúmu nígbà tí ó yá. A máa rojọ́ kùù ní gbogbo ìgbà tí ó bá ń mu wáìnì, a sì máa fi àwọn àṣeyọrí rẹ̀ yangàn. Ọ̀kan lára ohun tí ó burú jù lọ tí Alẹkisáńdà ṣe ni pé ó ṣìkà pa Kílítọ́sì ọ̀rẹ́ rẹ̀ nígbà tí ó bínú tí ó sì fara ya lẹ́yìn tí ọtí ti wọ̀ ọ́ lára. Ṣùgbọ́n Alẹkisáńdà dá ara rẹ̀ lẹ́bi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi ọjọ́ mẹ́ta wà lórí ibùsùn rẹ̀ láìjẹ láìsì mu ohunkóhun. Níkẹyìn, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣàṣeyọrí ní rírọ̀ ọ́ láti jẹun.

Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ìfẹ́ tí Alẹkisáńdà ní sí gbígba ògo sún un láti máa hu àwọn ìwà àìtọ́ mìíràn. Ó bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn ẹ̀sùn èké gbọ́ láìjiyàn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ àwọn ènìyàn níyà lọ́nà tí ó le koko jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, bí a ti mú kí Alẹkisáńdà gbà gbọ́ pé Fílótásì mọ̀ nípa sísapá tí àwọn kan sapá láti gbẹ̀mí rẹ̀, ó ní kí wọ́n pa àtòun àti Parmenio baba rẹ̀, tí ó jẹ́ alábàádámọ̀ràn rẹ̀ tí ó fọkàn tán tẹ́lẹ̀.

OHUN TÍ Ó ṢẸ́GUN ALẸKISÁŃDÀ

Gẹ́rẹ́ tí Alẹkisáńdà padà sí Bábílónì, ibà kọlù ú, kò sì bọ́ nínú rẹ̀. Lẹ́yìn tí Alẹkisáńdà ti gbé láyé fún kìkì ọdún méjìlélọ́gbọ̀n àti oṣù mẹ́jọ péré, ó juwọ́ sílẹ̀ fún ikú, ọ̀tá tí ó le kú jù lọ, ní June 13, ọdún 323 ṣááju Sànmánì Tiwa.

Gẹ́lẹ́ bí àwọn amòye ọmọ Íńdíà kan ṣe wí ni ó rí, pé: “Alẹkisáńdà Ọba, kìkì ìwọ̀nba ilẹ̀ tí olúkúlùkù ènìyàn dúró lé lórí ni ìní tirẹ̀; ìwọ sì rèé, tí o jẹ́ ènìyàn kan náà bí àwọn ènìyàn yòókù, yàtọ̀ sí ti pé ìgbòkègbodò àti àìsinmi tìrẹ pọ̀ gidigidi, o ń káàkiri gbogbo ayé ní ibi tí ó jìnnà réré sí ìlú ìbílẹ̀ tìrẹ, tí o ń yọ ara rẹ lẹ́nu, tí o sì ń kó ìyọnu bá àwọn ẹlòmíràn. Àmọ́ ṣá o, láìpẹ́ ikú yóò pa ọ́, ìní tìrẹ kò sì ní tayọ kìkì ìwọ̀nba ilẹ̀ tí a óò sìnkú rẹ sí.”

[Àpótí]

KÍ LO LÓYE?

• Kí ní jẹ́ ipò àtilẹ̀wá Alẹkisáńdà Ńlá?

• Kété lẹ́yìn tí Alẹkisáńdà jogún ìtẹ́ Makedóníà, ogun kí ni ó ń jà kiri?

• Ṣàpèjúwe díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ́gun Alẹkisáńdà.

• Kí ni a lè sọ nípa ìwà Alẹkisáńdà?

[Àwòrán ilẹ̀]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Àwọn Ibi tí Alẹkisáńdà Ṣẹ́gun

MAKEDÓNÍÀ

ÍJÍBÍTÌ

Bábílónì

Odò Indus

[Àwòrán]

Alẹkisáńdà

[Àwòrán]

Aristotle àti Alẹkisáńdà ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀

[Àwòrán]

[Àwòrán]

Àmì ẹ̀yẹ tí wọ́n sọ pé wọ́n yàwòrán Alẹkisáńdà Ńlá sí

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 162-163]

A PÍN ÌJỌBA GBÍGBÒÒRÒ KAN

BÍBÉLÌ sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìjọba Alẹkisáńdà Ńlá pé yóò fọ́ àti pé yóò pín ṣùgbọ́n pípín tí yóò pín “kì í ṣe fún ìran àtẹ̀lé rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 11:3, 4) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, láàárín ọdún mẹ́rìnlá lẹ́yìn ikú òjijì tí ó pa Alẹkisáńdà ní ọdún 323 ṣááju Sànmánì Tiwa, wọ́n dìtẹ̀ pa ọmọ rẹ̀ Alẹkisáńdà Kẹrin àti Hérákù, ọmọ àlè tí ó bí.

Ní nǹkan bí ọdún 301 ṣááju Sànmánì Tiwa, mẹ́rin nínú àwọn ọ̀gágun Alẹkisáńdà ti gbé ara wọn sípò agbára lórí ilẹ̀ ọba gbígbòòrò tí aṣáájú wọn dá sílẹ̀. Ọ̀gágun Kasáńdà gba àkóso ilẹ̀ Makedóníà àti ti Gíríìsì. Ọ̀gágun Lisimákù gba Éṣíà Kékeré àti Tírésì. Ilẹ̀ Mesopotámíà àti Síríà di ti Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní Níkétọ̀. Pẹ́tólẹ́mì Lágọ́sì, tàbí Pẹ́tólẹ́mì Kìíní sì ṣàkóso ilẹ̀ Íjíbítì àti Palẹ́sìnì. Bí ìjọba Hélénì, tàbí ìjọba Gíríìkì mẹ́rin ṣe dìde láti inú ìjọba ńlá kan ṣoṣo ti Alẹkisáńdà nìyẹn.

Nínú ìjọba Hélénì mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ìṣàkóso ti Kasáńdà ni ó wà fún ìgbà kúkúrú jù lọ. Ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí Kasáńdà gorí àlééfà, gbogbo ìran ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin kú tán pátá, ní ọdún 285 ṣááju Sànmánì Tiwa, Lisimákù bá gba apá tí ó jẹ́ ti Yúróòpù nínú Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì. Ní ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà, Lisimákù ṣubú níwájú Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní Níkétọ̀, tí ó fi di ẹni tí ó ń ṣàkóso apá tí ó pọ̀ jù lọ nínú àgbègbè ìpínlẹ̀ tí ó jẹ́ ti Éṣíà. Sẹ̀lẹ́úkọ́sì wá di àkọ́kọ́ nínú àwọn ọba tí ó ń jẹ láti ìlà Sẹ̀lẹ́úkọ́sì ní Síríà. Ó kọ́ Áńtíókù ní Síríà, ó sì sọ ọ́ di olú ìlú rẹ̀ tuntun. Wọ́n dìtẹ̀ pa Sẹ̀lẹ́úkọ́sì lọ́dún 281 ṣááju Sànmánì Tiwa, ṣùgbọ́n ìlà ọba tí ó ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ń bá a lọ láti ṣàkóso títí di ọdún 64 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí Ọ̀gágun Pompey ará Róòmù fi sọ Síríà di ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù.

Ìjọba ti ìlà Pẹ́tólẹ́mì ni ó wà fún ìgbà pípẹ́ jù lọ nínú ọ̀nà mẹ́rin tí ilẹ̀ ọba Alẹkisáńdà pín sí. Pẹ́tólẹ́mì Kìíní di ẹni tí ń lo orúkọ oyè náà, ọba, ní ọdún 305 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó sì di àkọ́kọ́ nínú àwọn ọba, tàbí àwọn Fáráò ilẹ̀ Íjíbítì tí ó jẹ́ ará Makedóníà. Bí ó ṣe sọ Alẹkisáńdíríà di olú ìlú rẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ ètò ìdàgbàsókè ìlú ńlá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ibi Ìkówèésí Alẹkisáńdíríà, tí òkìkí rẹ̀ kàn gan-an, ni ọ̀kan nínú iṣẹ́ ìkọ́lé tí ó ga jù lọ tí ó dáwọ́ lé. Pẹ́tólẹ́mì mú Démétíríù Fálérọ́sì, gbajúgbajà ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan, tí ó jẹ́ ará Áténì, wá láti Gíríìsì, kí ó lè wá ṣàbójútó iṣẹ́ ìkọ́lé tí ó dáwọ́ lé náà. A ròyìn rẹ̀ pé, ní nǹkan bí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, àkájọ ìwé tí ó wà níbi ìkówèésí náà jẹ́ mílíọ̀nù kan. Àwọn ọba tí ó ń jẹ láti ìlà Pẹ́tólẹ́mì ń bá a lọ láti máa ṣàkóso ní ilẹ̀ Íjíbítì títí ó fi ṣubú sọ́wọ́ ilẹ̀ Róòmù ní ọdún 30 ṣááju Sànmánì Tiwa. Róòmù wá di agbára ayé pàtàkì ní ipò Gíríìsì.

Kí Lo Lóye?

• Báwo ni a ṣe pín ilẹ̀ ọba gbígbòòrò tí ó jẹ́ ti Alẹkisáńdà?

• Àwọn ọba láti ìlà Sẹ̀lẹ́úkọ́sì ń ṣàkóso ní Síríà títí di ìgbà wo?

• Ìgbà wo ni ìjọba àwọn ọba tí ń jẹ lórí Íjíbítì láti ìlà Pẹ́tólẹ́mì dópin?

[Àwòrán ilẹ̀]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ọ̀NÀ TÍ ILẸ̀ ỌBA ALẸKISÁŃDÀ PÍN SÍ

Kasáńdà

Lisimákù

Pẹ́tólẹ́mì Kìíní

Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní

[Àwọn àwòrán]

Pẹ́tólẹ́mì Kìíní

Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 139]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÀWỌN AGBÁRA AYÉ INÚ ÀSỌTẸ́LẸ̀ DÁNÍẸ́LÌ

Ère arabarìbì (Dáníẹ́lì 2:31-45)

Ẹranko mẹ́rin láti inú òkun (Dáníẹ́lì 7:3-8, 17, 25)

ILẸ̀ ỌBA BÁBÍLÓNÌ láti ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa

MÍDÍÀ ÒUN PÁṢÍÀ láti ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa

GÍRÍÌSÌ láti ọdún 331 ṣááju Sànmánì Tiwa

RÓÒMÙ láti ọdún 30 ṣááju Sànmánì Tiwa

AGBÁRA AYÉ GẸ̀Ẹ́SÌ ÀTI AMẸ́RÍKÀ láti ọdún 1763 Sànmánì Tiwa

AYÉ TÍ Ó PÍN YẸ́LẸYẸ̀LẸ NÍ TI Ọ̀RÀN ÌṢÈLÚ ní àkókò òpin

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 128]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 147]